Yoruba

Translation: yor-shaykhaburahima

Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Ìlànà

Surah 1

[1] Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[2] Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[3] Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[4] Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san

[5] Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá oore sí

[6] Jíjọ́sìn fún Allāhu níkan ṣoṣo àti dídúró ṣinṣin nínú ìjọ́sìn Rẹ̀ ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah Āli ‘Imrọ̄n “Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ sínú ’Islām ọ̀nà tààrà.” Nítorí náà

[7] ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún,yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasara)

Abaamú

Surah 2

[1] ’Alif lām mīm

[2] Èyí ni Tírà náà, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìmọ̀nà ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[3] àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú (ìró) ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn

[4] àti àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, tí wọ́n sì ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[5] Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè

[6] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o ò kìlọ̀ fún wọn, wọn kò níí gbàgbọ́

[7] Allāhu fi èdídí dí ọkàn wọn àti ìgbọ́rọ̀ wọn. Èbìbò sì bo ìríran wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn

[8] Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.” Wọn kì í sì ṣe onígbàgbọ́ òdodo

[9] Wọ́n ń tan Allāhu àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo jẹ. Wọn kò sì lè tan ẹnì kan jẹ bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura

[10] Àrùn kan wà nínú ọkàn wọn, nítorí náà Allāhu ṣe àlékún àrùn fún wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn nítorí pé wọ́n ń parọ́

[11] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Àwa ni alátùn-únṣe.”

[12] Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òbìlẹ̀jẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò fura

[13] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ ní òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe gbàgbọ́.” Wọ́n á wí pé: “Ṣé kí á gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn òmùgọ̀ ṣe gbàgbọ́ ni?” Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òmùgọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀

[14] Nígbà tí wọ́n bá pàdé àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì kù wọ́n ku àwọn (ẹni) èṣù wọn, wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwa ń bẹ pẹ̀lú yín, àwa kàn ń ṣe yẹ̀yẹ́ ni.”

[15] Allāhu máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sì máa mú wọn lékún sí i nínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà. tí àwọn ìṣe náà jẹ́ ìṣe t’ó dúró sórí fífi orúkọ ìṣe ẹ̀dá sọ orúkọ ẹ̀san ìṣe náà. Irú rẹ̀ l’ó ṣẹlẹ̀ nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe olùṣeyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ó máa ń ṣe yẹ̀yẹ́) tàbí oníyẹ̀yẹ́ (ẹni tí ẹ̀dá lè fi ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹnì kan kò sì níí máa ṣe yẹ̀yẹ́ àfi kí ó jẹ́ aláwàdà oníranù. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kì í ṣe àwàdà Allāhu kì í ṣe ẹlẹ́tàn. Ẹnì kan kò níí jẹ́ ẹlẹ́tàn àfi kí ó jẹ́ òpùrọ́ olùyapa-àdéhùn. Allāhu kì í ṣe òpùrọ́. Allāhu gan-an ni Òdodo. Bákan náà

[16] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà. Nítorí náà, òkòwò wọn kò lérè, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà

[17] Àpèjúwe wọn dà bí àpèjúwe ẹni tí ó tan iná, ṣùgbọ́n nígbà tí ìmọ́lẹ̀ tàn sí àyíká rẹ̀ tán, Allāhu mú ìmọ́lẹ̀ wọn lọ, Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú àwọn òkùnkùn; wọn kò sì ríran mọ́

[18] Adití, ayaya, afọ́jú ni wọ́n; nítorí náà wọn kò níí ṣẹ́rí padà

[19] Tàbí (àpèjúwe wọn) dà bí òjò ńlá tí ń rọ̀ láti sánmọ̀. Ó mú àwọn òkùnkùn, àrá sísán àti mọ̀nàmọ́ná lọ́wọ́. Wọ́n ń fi ìka wọn sínú etí wọn nítorí igbe àrá sísán fún ìbẹ̀rù ikú. Allāhu sì yí àwọn aláìgbàgbọ́ ká

[20] Mọ̀nàmọ́ná náà fẹ́ẹ̀ mú ìríran wọn lọ. Nígbàkígbà tí ó bá tan ìmọ́lẹ̀ sí wọn, wọ́n á rìn lọ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá sì ṣóòòkùn mọ́ wọn, wọ́n á dúró si. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá gba ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[21] Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná)

[22] (Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà, Ó sọ omi òjò kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fun yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́)

[23] Tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa, nítorí náà, ẹ mú sūrah kan wá bí irú rẹ̀, kí ẹ sì pe àwọn ẹlẹ́rìí yín, yàtọ̀ sí Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[24] Tí ẹ ò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ò wulẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà ẹ ṣọ́ra fún Iná, èyí tí ìkoná rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn àti òkúta tí Wọ́n pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[25] Fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé, dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan ń bẹ fún wọn, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Nígbàkígbà tí A bá p’èsè jíjẹ-mímu kan fún wọn nínú èso rẹ̀, wọn yóò sọ pé: “Èyí ni wọ́n ti pèsè fún wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” – Wọ́n mú un wá fún wọn ní ìrísí kan náà ni (àmọ́ pẹ̀lú adùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). – Àwọn ìyàwó mímọ́ sì ń bẹ fún wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀

[26] Dájúdájú Allāhu kò níí tijú láti fí ohun kan bí ẹ̀fọn tàbí ohun tí ó jù ú lọ ṣàkàwé ọ̀rọ̀. Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò wí pé: “Kí ni ohun tí Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àkàwé yìí?” Allāhu ń fi ṣi lọ́nà. Ó sì ń fi tọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sọ́nà. Kò sì níí fi ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àyàfi àwọn arúfin

[27] Àwọn t’ó ń yẹ májẹ̀mu Allāhu lẹ́yìn tí májẹ̀mu náà ti fìdí múlẹ̀, wọ́n tún ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò

[28] Báwo ni ẹ ṣe ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu ná! Bẹ́ẹ̀ sì ni òkú ni yín (tẹ́lẹ̀), Ó sì sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí

[29] Òun ni Ẹni tí Ó dá ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ fun yín pátápátá. Lẹ́yìn náà, Ó wà l’ókè sánmọ̀, Ó sì ṣe wọ́n tógún régé sí sánmọ̀ méje. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[30] ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ṣíwájú ìṣẹ̀dá sánmọ̀ gẹ́gẹ́ bí āyah inú sūrah Baƙọrah yẹn ṣe fi rinlẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ni āyah sūrah an-Nāzi‘āt ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sì lo ọ̀rọ̀ t’ó túmọ̀ sí ìṣẹ̀dá ilẹ̀ nínú āyah t’Ó ti dárúkọ ilẹ̀ ìyẹn āyah 30 nínú sūrah ìṣẹ̀dá gbogbo ohun t’ó máa wà nínú ilẹ̀ ní àwọn igi àwọn ibúdò 30 (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò fi àrólé kan sórí ilẹ̀.” Wọ́n sọ pé: “Ṣé Ìwọ yóò fi ẹni tí ó máa ṣèbàjẹ́ síbẹ̀, tí ó sì máa tẹ̀jẹ̀ sílẹ̀? Àwa sì ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Ọ. A sì ń fi ògo fún Ọ!" Ó sọ pé: “Dájúdájú Èmi mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

[31] Allāhu fi àwọn orúkọ náà, gbogbo wọn pátápátá, mọ Ādam. Lẹ́yìn náà, Ó kó wọn síwájú àwọn mọlāika, Ó sì sọ pé: “Ẹ sọ àwọn orúkọ wọ̀nyí fún Mi, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

[32] Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò sí ìmọ̀ kan fún wa àyàfi ohun tí O fi mọ̀ wá. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”

[33] Ó sọ pé: “Ādam, sọ orúkọ wọn fún wọn.” Nígbà tí ó sọ orúkọ wọn fún wọn tán, Ó sọ pé: “Ṣé Èmi kò sọ fun yín pé dájúdájú Èmi nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Mo sì nímọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́?”

[34] (Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀, ó sì ṣe ìgbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́

[35] A sì sọ pé: “Ādam, ìwọ àti ìyàwó rẹ, ẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ ní gbẹdẹmukẹ ní ibikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí, kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.”

[36] Àmọ́ Èṣù yẹ àwọn méjèèjì lẹ́sẹ̀ kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú ibi tí wọ́n wà. A sì sọ pé: "Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín jẹ́ fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fun yín lórí ilẹ̀ fún ìgbà (díẹ̀).”

[37] Lẹ́yìn náà, (Ànábì) Ādam rí àwọn ọ̀rọ̀ kan gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[38] A sọ pé : “Gbogbo yín, ẹ sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Nígbà tí ìmọ̀nà bá dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, ìpáyà kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́

[39] Àwọn t’ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.”

[40] Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo ṣe fun yín. Ẹ mú májẹ̀mu Mi ṣẹ, Mo máa mú (ẹ̀san) májẹ̀mu yín ṣẹ. Èmi nìkan ni kí ẹ sì páyà

[41] Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Mo sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi l’ówó pọ́ọ́kú.Èmi nìkan ṣoṣo ni kí ẹ sì bẹ̀rù

[42] Ẹ má da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì má fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo)

[43] Ẹ kírun, ẹ yọ zakāh, kí ẹ sì dáwọ́ tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun)

[44] Ṣé ẹ̀yin yóò máa pa àwọn ènìyàn l’áṣẹ ohun rere, ẹ sì ń gbàgbé ẹ̀mí ara yín, ẹ̀yin sì ń ké Tírà, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni

[45] Ẹ wá oore (Allāhu) pẹ̀lú sùúrù àti ìrun kíkí. Dájúdájú ó lágbára (láti ṣe bẹ́ẹ̀) àyàfi fún àwọn olùpáyà (Allāhu)

[46] àwọn t’ó mọ̀ pé dájúdájú àwọn yóò pàdé Olúwa wọn, àti pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[47] Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo fi ṣèdẹ̀ra fun yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fun yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín)

[48] Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò níí gba ìṣìpẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.1 A ò sì níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.2 àwọn āyah mìíràn sọ pé ìṣìpẹ̀ wà.” Wọ́n ní “Ìtakora nìyẹn.” 123 àti 254 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:51. Àmọ́ àwọn āyah t’ó ń sọ pé ìṣìpẹ̀ máa wà lọ́jọ́ Àjíǹde ń sọ nípa àwọn májẹ̀mú tí ó wà fún ìṣìpẹ̀ olùṣìpẹ̀ àti olùṣìpẹ̀-fún. Irúfẹ́ àwọn āyah náà ni sūrah al-Baƙọrah

[49] (Ẹ rántí) nígbà tí A gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, tí wọ́n ń dúńbú àwọn ọmọkùnrin yín, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn obìnrin yín ṣẹ̀mí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín

[50] (Ẹ rántí) nígbà tí A pín agbami odò sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fun yín, A sì gbà yín là. A tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì. Ẹ̀yin náà sì ń wò (wọ́n nínú agbami odò)

[51] (Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe àdéhùn ogójì òru fún (Ànábì) Mūsā. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín

[52] Lẹ́yìn náà, A mójú kúrò fun yín lẹ́yìn ìyẹn nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu)

[53] (Ẹ rántí) nígbà tí A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà nítorí kí ẹ lè mọ̀nà

[54] (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú ẹ̀yin ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara yín nípa sísọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín, kí àwọn tí kò bọ màálù pa àwọn t’ó bọ ọ́ láààrin yín. Ìyẹn l’óore jùlọ fun yín ní ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà yín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[55] (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí gbà ọ́ gbọ́ àfi kí á rí Allāhu ní ojúkorojú.” Nítorí náà, ohùn igbe láti inú sánmọ̀ gba yín mú, ẹ sì ń wò bọ̀ọ̀

[56] Lẹ́yìn náà, A ji yín dìde lẹ́yìn ikú yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu)

[57] A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fun yín. A sì tún sọ (ohun mímu) mọnnu àti (ohun jíjẹ) salwā kalẹ̀ fun yín. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fun yín. Wọn kò sì ṣàbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí

[58] (Ẹ rántí) nígbà tí A sọ pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí. Ẹ jẹ nínú ìlú náà níbikíbi tí ẹ bá fẹ́ ní gbẹdẹmukẹ. Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùtẹríba. Kí ẹ sì wí pé: “Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.” A óò forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere

[59] Àwọn t’ó ṣàbòsí yí ọ̀rọ̀ náà padà (sí n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. Nítorí náà, A sọ ìyà kalẹ̀ láti sánmọ̀ lé àwọn t’ó ṣàbòsí lórí nítorí pé wọ́n ń rú òfin

[60] (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā tọrọ omi fún ìjọ rẹ̀. A sì sọ pé: “Fi ọ̀pá rẹ na òkúta.” Orísun omi méjìlá sì ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Ìran kọ̀ọ̀kan sì ti mọ ibùmu wọn. Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu nínú arísìkí Allāhu. Ẹ má balẹ̀ jẹ́ ní ti òbìlẹ̀jẹ́

[61] (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí ṣe ìfaradà lórí oúnjẹ ẹyọ kan. Nítorí náà, pe Olúwa rẹ fún wa. Kí Ó mú jáde fún wa nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde bí ewébẹ̀ rẹ̀, kùkúḿbà rẹ̀, ọkà bàbà rẹ̀, ẹ̀wà rẹ̀ àti àlùbọ́sà rẹ̀.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò fi èyí tó yẹpẹrẹ pààrọ̀ èyí tí ó dára jùlọ ni? Ẹ sọ̀kalẹ̀ sínú ìlú (mìíràn). Dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún ń bẹ (níbẹ̀) fun yín.” A sì mú ìyẹpẹrẹ àti òṣì bá wọn. Wọ́n sì padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n sì ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-àlà

[62] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn yẹhudi, nasara àti àwọn sọ̄bi’u; ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́

[63] Ẹ rántí nígbà tí A gba àdéhùn yín, A sì gbé àpáta wá sókè orí yín, (A sì sọ pé): “Ẹ gbá ohun tí A fun yín mú dáradára, kí ẹ sì rántí ohun t’ó wà nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu)

[64] Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín, ẹ̀yin ìbá wà nínú ẹni òfò

[65] Dájúdájú ẹ mọ àwọn t’ó kọjá ẹnu-àlà nínú yín nípa ọjọ́ Sabt. A sì sọ fún wọn pé: "Ẹ di ọ̀bọ, ẹni-ìgbéjìnnà sí ìkẹ́

[66] A sì ṣe é ní àríkọ́gbọ́n fún ẹni t’ó ṣojú rẹ̀ àti ẹni t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. (Ó tún jẹ́) ẹ̀kọ́ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[67] (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa abo màálù kan.” Wọ́n wí pé: “Ṣé ò ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ ni!” Ó sọ pé: "Mò ń sádi Allāhu níbi kí n̄g jẹ́ ara àwọn òpè

[68] Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó fi yé wa, èwo ni.” Ó sọ pé: "Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ ògbólógbòó, kò sì níí jẹ́ gódógbó. Ó máa wà láààrin (méjèèjì) yẹn. Nítorí náà, ẹ ṣe ohun tí Wọ́n ń pa yín láṣẹ

[69] Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó fi yé wa, kí ni àwọ̀ rẹ̀.” Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù, aláwọ̀ omi-ọsàn ni. Àwọ̀ rẹ̀ yó sì mọ́ fónífóní, tí ó máa dùn-ún wò l’ójú àwọn olùwòran

[70] Wọ́n wí pé: "Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó fi yé wa, èwo ni. Dájúdájú àwọn abo màálù jọra wọn lójú wa. Àti pé dájúdájú, tí Allāhu bá fẹ́, àwa máa mọ̀nà (tí a ó gbà rí i)

[71] Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ màálù yẹpẹrẹ tí ń roko. Kò sì níí máa fomi wọ́n oko. Ó máa ní àlàáfíà, kò sì níí ní àbàwọ́n kan lára.” Wọ́n wí pé: “Nísinsìn yìí l’o mú òdodo wá.” Wọ́n sì pa màálù náà. Wọ́n fẹ́ẹ̀ má ṣe é mọ́

[72] (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ pa ẹnì kan, ẹ sì ń tì í síra yín. Allāhu yó sì ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́

[73] Nítorí náà, A sọ pé: “Ẹ fi burè kan (lára màálù) lu (òkú náà).” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ òkú di alààyè. Ó sì ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè

[74] Lẹ́yìn náà, ọkàn yín le lẹ́yìn ìyẹn. Ó sì dà bí òkúta tàbí líle t’ó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn òkúta tí àwọn odò ń ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó máa sán kànkàn. Omi sì máa jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó ń wó lulẹ̀ gbì fún ìpáyà Allāhu. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[75] Ǹjẹ́ ẹ lérò pé wọn yóò gbà yín gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé igun kan nínú wọn kúkú ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n á yí i padà sódì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ ọ yé; wọ́n sì mọ̀

[76] Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku apá kan wọn ku apá kan, wọ́n á wí pé: “Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Allāhu ti ṣípayá rẹ̀ fun yín, kí wọ́n lè fi jà yín níyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín? Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni!”

[77] Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀

[78] Àti pé ó wà nínú wọn, àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, tí wọn kò nímọ̀ nípa Tírà àfi àwọn ọ̀rọ̀-irọ́. Kí ni wọ́n (ń sọ) bí kò ṣe pé wọ́n ń sàròsọ

[79] Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ Tírà, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Nítorí kí wọ́n lè tà á ní owó pọ́ọ́kú. Ègbé ni fún wọn sẹ́ nípa ohun tí ọwọ́ wọn kọ. Ègbé sì ni fún wọn pẹ̀lú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ

[80] Wọ́n sì wí pé: “Iná kò lè fọwọ́ bà wá tayọ ọjọ́ t’ó lóǹkà.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ti rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Allāhu ni?”Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni

[81] Rárá (Iná kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí); ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ibi kan, tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tún yí i ká, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[82] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[83] (Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ‘Isrọ̄’īl pé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ọlọ́hun kan àyàfi Allāhu. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì, ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù. Ẹ bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ rere. Ẹ kírun, kí ẹ sì yọ Zakāh. Lẹ́yìn náà lẹ pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú yín. Ẹ̀yin sì ń gbúnrí (kúrò níbi àdéhùn)

[84] (Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín pé ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ yin sílẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ léra yín jáde kúrò nínú ilé yín. Lẹ́yìn náà, ẹ fi rinlẹ̀, ẹ sì ń jẹ́rìí sí i

[85] Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin wọ̀nyí l’ẹ̀ ń p’ara yín. Ẹ tún ń lé apá kan nínú yín jáde kúrò nínú ilé wọn. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àti àbòsí ṣèrànwọ́ (fún àwọn ọ̀tá) lórí wọn. Tí wọ́n bá sì wá ba yín (tí wọ́n ti di) ẹrú, ẹ̀yin ń rà wọ́n (láti fi’ra yín ṣẹrú). Èèwọ̀ sì fẹ̀ẹ̀kan ni fun yín láti lé wọn jáde. Ṣé ẹ̀yin yóò gba apá kan Tírà gbọ́, ẹ sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan? Nítorí náà, kí ni ẹ̀san fún ẹni tó ṣè yẹn nínú yín bí kò ṣe àbùkù nínú ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọjọ́ Àjíǹde, wọ́n sì máa dá wọn padà sínú ìyà tó le jùlọ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[86] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀run ra ìṣẹ̀mí ayé. Nítorí náà, A ò níí gbé ìyà fúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́

[87] Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì mú àwọn Òjíṣẹ́ wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé lẹ́yìn rẹ̀. A tún fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. A tún fún ní agbára nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, Mọlāika Jibrīl). Ṣé gbogbo ìgbà tí Òjíṣẹ́ kan bá wá ba yín pẹ̀lú ohun tí ọkàn yín kò fẹ́ ni ẹ ó máa ṣègbéraga? Ẹ sì pe apá kan (àwọn Ànábì) ní òpùrọ́, ẹ sì ń pa apá kan

[88] Wọ́n sì wí pé: “Èbìbò bò wá lọ́kàn.” Kò sì rí bẹ́ẹ̀. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn ni nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Ṣebí díẹ̀ ni wọ́n ń gbàgbọ́

[89] Nígbà tí Tírà kan sì dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ń fi ìdí òdodo múlẹ̀ nípa ohun tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti ń tọrọ ìṣẹ́gun lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àmọ́ nígbà tí ohun tí wọ́n nímọ̀ nípa rẹ̀ dé bá wọn, wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn aláìgbàgbọ́

[90] Aburú ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn nípa bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ní ti ìlara pé Allāhu ń sọ (Tírà) kalẹ̀ nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Wọ́n sì padà pẹ̀lú ìbínú (mìíràn) lórí ìbínú (Allāhu tí ó ti wà lórí wọn tẹ́lẹ̀). Ìyà tí í yẹpẹrẹ (ẹ̀dá) sì ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́

[91] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa.” Wọ́n sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun t’ó wà lẹ́yìn rẹ̀, tí ó sì ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú wọn. Sọ pé: “Nítorí kí ni ẹ fi ń pa àwọn Ànábì Allāhu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[92] Àti pé dájúdájú (Ànábì) Mūsā ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.”

[93] (Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, A sì gbé àpáta s’ókè orí yín, (A sọ pé:) "Ẹ gbá ohun tí A fun yín mú dáradára. Kí ẹ sì tẹ́tí gbọ́rọ̀." Wọ́n wí pé: "A gbọ́ (àṣẹ), a sì yapa (àṣẹ)." Wọ́n ti kó ìfẹ́ bíbọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù sínú ọkàn wọn nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ wọn. Sọ pé: "Aburú ni ohun tí ìgbàgbọ́ (ìbọ̀rìṣà) yín ń pa yín láṣẹ rẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[94] Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé tiyín nìkan ni Ilé Ìkẹyìn tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu, tí kò sì níí jẹ́ ti àwọn ènìyàn (mìíràn), ẹ tọrọ ikú, tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[95] Wọn kò níí tọrọ ikú láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí

[96] Dájúdájú o máa rí wọn pé àwọn ni ènìyàn t’ó l’ójú kòkòrò jùlọ nípa ìṣẹ̀mí ayé, (wọ́n tún l’ójú kòkòrò ju) àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ. Ìkọ̀ọ̀kan wọn ń fẹ́ pé tí A bá lè fún òun ní ẹgbẹ̀rún ọdún lò láyé. Bẹ́ẹ̀ sì ni, kì í ṣe ohun tí ó máa là á nínú ìyà ni pé kí Á fún un ní ìṣẹ̀mí gígùn lò. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[97] Sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún (mọlāika) Jibrīl, (ó ti di ọ̀tá Allāhu) nítorí pé dájúdájú (mọlāika) Jibrīl ló mú al-Ƙur’ān wá sínú ọkàn rẹ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Al-Ƙur’ān sì ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[98] Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, Jibrīl àti Mīkāl, dájúdájú Allāhu ni ọ̀tá fún àwọn aláìgbàgbọ́

[99] Dájúdájú A ti sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ fún ọ. Ẹnì kan kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ àyàfi àwọn arúfin

[100] Àti pé ṣé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá dá májẹ̀mu kan ni apá kan nínú wọn yóò máa jù ú nù? Rárá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni kò gbàgbọ́

[101] Àti pé nígbà tí Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu dé bá wọn, tí ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú ohun t’ó wà pẹ̀lú wọn, apá kan nínú àwọn tí A fún ní Tírà gbe Tírà Allāhu jù s’ẹ́yìn lẹ́yìn wọn bí ẹni pé wọn kò mọ̀ (pé àsọọ́lẹ̀ nípa Ànábì s.a.w. wà nínú rẹ̀)

[102] Wọ́n sì tẹ̀lé ohun tí àwọn èṣù àlùjànnú ń kà (fún wọn nínú idán) lásìkò ìjọba (Ànábì) Sulaemọ̄n. (Ànábì) Sulaemọ̄n kò sì ṣàì gbàgbọ́, ṣùgbọ́n àwọn èṣù àlùjànnú ni wọ́n ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán. Àwa kò sì sọ (idán) kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjì náà. (Àmọ́ àwọn èṣù àlùjànnú wọ̀nyí) Hārūt àti Mọ̄rūt ní (ìlú) Bābil (ni wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn nídán). Wọn kò sì níí kọ́ ẹnikẹ́ni àyàfi kí wọ́n wí pé: "Àdánwò ni wá. Nítorí náà, má di kèfèrí." Wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọn yóò fi ṣòpínyà láààrin ọmọnìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn àlùjànnú méjèèjì. - Wọn kò sì lè kó ìnira bá ẹnikẹ́ni àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. - Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó máa kó ìnira bá wọn, tí kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọ́n kúkú ti mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ra idán, kò níí sí ìpín rere kan fún un ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Aburú sì ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀. tí àwọn onímọ̀ mú wá lórí rẹ̀. Má ṣe ṣíjú wo ìtúmọ̀ mìíràn … bí ìtàn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn ọtí mímu àti ẹ̀sùn ìpànìyàn kan àwọn mọlāika… Ìpìlẹ̀ àdìsọ́kàn tí a ní sí àwọn mọlāika yó forí sánpọ́n nípa pípe Hārūt àti Mọ̄rūt ní mọlāika. Àwọn mọlāika ni ẹni tí Allāhu ní àfọkàntán sí lórí ìmísí Rẹ̀ tí Ó fi rán wọn. Àwọn sì ni aṣojú Allāhu fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ wo sūrah at-Tahrīm; 66:6 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:26-27…” al-Ƙurtubiy. bí Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbàgbọ́ òdodo tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán an níṣẹ́ sí wọn bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn èṣù àlùjànnú kan ń lọ bá àwọn ènìyàn láti máa kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ idán láti máa fi tako ìgbàgbọ́ òdodo tí wọ́n ń gbọ́ lọ́dọ̀ Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Níkété tí ìró aburú yìí détí ìgbọ́ Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó páṣẹ láti gba gbogbo àkọsílẹ̀ idán náà lọ́wọ́ wọn. Ó sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀

[103] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ẹ̀san tí ó máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’óore jùlọ (fún wọn), tí wọ́n bá mọ̀

[104] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má sọ pé “rọ̄‘inā”. (Àmọ́) ẹ sọ pé “unṭḥurnā” , kí ẹ sì máa tẹ́tí gbọ́ (ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́

[105] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn ọ̀ṣẹbọ kò fẹ́ kí wọ́n sọ oore kan kan kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Allāhu sì ń fi ìkẹ́ Rẹ̀ ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu sì ni Olóore ńlá

[106] A ò níí fi āyah kan pa āyah kan rẹ́ tàbí kí Á fi sílẹ̀ (bẹ́ẹ̀ ní ohun kíké nìkan), A máa mú èyí t’ó dára jù ú lọ tàbí irú rẹ̀ wá. Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[107] Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu

[108] Tàbí ẹ fẹ́ máa bèèrè (ọ̀rọ̀kọrọ̀) lọ́wọ́ Òjíṣẹ́ yín ni gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe bèèrè (ọ̀rọ̀kọrọ̀) lọ́wọ́ (Ànábì) Mūsā ṣíwájú? Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àìgbàgbọ́ rọ́pò ìgbàgbọ́, dájúdájú ó ti ṣìnà (kúrò) l’ójú ọ̀nà tààrà

[109] Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A fún ní Tírà ń fẹ́ láti da yín padà sípò kèfèrí lẹ́yìn tí ẹ ti ní ìgbàgbọ́ òdodo, ní ti kèéta láti inú ẹ̀mí wọn, (àti) lẹ́yìn tí òdodo (’Islām) ti fojú hàn sí wọn. Nítorí náà, ẹ foríjìn wọ́n, kí ẹ ṣàmójú kúrò fún wọn (nípa ìnira tí wọ́n ń fi kàn yín) títí Allāhu yó fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá (láti ja wọ́n lógun). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[110] Ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh; ohunkóhun tí ẹ bá sì tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín ní rere, ẹ máa bá a lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[111] Wọ́n wí pé: “Ẹnì kan kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi ẹni tí ó bá jẹ́ yẹhudi tàbí nasara.” Ìyẹn ni ìfẹ́-ọkàn wọn. Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[112] Bẹ́ẹ̀ kọ́ (wọn kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi) ẹni tí ó bá ju ara rẹ̀ sílẹ̀ (nínú ’Islām) fún Allāhu, tí ó sì jẹ́ olùṣe rere. Nítorí náà, ẹ̀san (iṣẹ́) rẹ̀ ń bẹ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́

[113] Àwọn yẹhudi wí pé: “Àwọn nasara kò rí n̄ǹkan kan ṣe (nínú ẹ̀sìn).” Àwọn nasara náà wí pé: “Àwọn yẹhudi kò rí n̄ǹkan kan ṣe (nínú ẹ̀sìn.)” Wọ́n sì ń ké Tírà! Báyẹn ni àwọn tí kò nímọ̀ ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Nítorí náà, Allāhu á dájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí

[114] Àti pé ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tí ó ṣe àwọn mọ́sálásí Allāhu ní èèwọ̀ láti ṣèrántí orúkọ Allāhu nínú rẹ̀, tí ó tún ṣiṣẹ́ lórí ìparun àwọn mọ́sálásí náà? Àwọn wọ̀nyẹn, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti wọ inú rẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Àbùkù ń bẹ fún wọn n’ílé ayé. Ní ọ̀run, ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn

[115] Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Nítorí náà, ibikíbi tí ẹ bá dojú kọ ibẹ̀ yẹn náà ni ƙiblah Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀

[116] Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un! Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, (àmọ́) tiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀

[117] Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni (Allāhu). Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀

[118] Àwọn tí kò nímọ̀ wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń bá wa sọ̀rọ̀ ni tàbí kí àmì kan wá bá wa (àwa ìbá gbàgbọ́)?” Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Ọkàn wọn jọra wọn. A kúkú ti ṣe àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú

[119] Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ (fún gbogbo ayé). Wọn kò sì níí bi ọ́ léèrè nípa àwọn èrò inú Iná

[120] Àwọn yẹhudi àti nasara kò níí yọ́nú sí ọ títí o fi máa tẹ̀lé ẹ̀sìn wọn. Sọ pé: “Dájúdajú ìmọ̀nà ti Allāhu ni ìmọ̀nà.” Dájúdajú tí o bá sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn lẹ́yìn èyí tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀ (’Islām), kò níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu

[121] Àwọn tí A fún ní Tírà (al-Ƙur’ān), wọ́n ń ké e ní kíké ẹ̀tọ́. Àwọn wọ̀nyẹn gbà á gbọ́ ní òdodo. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni ẹni òfò

[122] Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìkẹ́ Mi, èyí tí Mo ṣe fun yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fun yín lórí àwọn

[123] Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò sì níí gba ààrọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣìpẹ̀ kan kò níí wúlò fún un. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́

[124] (Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa fi àwọn ọ̀rọ̀ kan dán (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wò. Ó sì parí wọn ní pípé. (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Èmi yó ṣe ọ́ ní aṣíwájú fún àwọn ènìyàn.” (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àti nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi.” (Allāhu) sọ pé: "Àdéhùn Mi (láti sọ ẹnì kan di Òjíṣẹ́) kò níí tẹ àwọn alábòsí lọ́wọ́

[125] (Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe Ilé (Kaaba) ní àyè tí àwọn ènìyàn yóò máa wá àti àyè ìfàyàbalẹ̀. Kí ẹ sì mú ibùdúró ’Ibrọ̄hīm ní ibùkírun. A sì pa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl láṣẹ pé “Ẹ ṣe Ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, àwọn olùkóraró sínú rẹ̀ àti àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún, àwọn olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun)

[126] (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì pèsè àwọn èso fún àwọn ará ibẹ̀ (ìyẹn) ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹyìn.” (Allāhu) sọ pé: "Àti ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò fún un ní ìgbádùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, Mo máa taari rẹ̀ sínú ìyà Iná. Ìkángun náà sì burú

[127] (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ismọ̄‘īl gbé àwọn ìpìlẹ̀ Ilé náà dúró. (Wọ́n ṣàdúà pé) "Olúwa wa, gbà á lọ́wọ́ wa, dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[128] Olúwa wa, ṣe wá ní mùsùlùmí fún Ọ. Kí O sì ṣe nínú àrọ́mọdọ́mọ wa ní ìjọ mùsùlùmí fún Ọ. Fi ìlànà ẹ̀sìn wa hàn wá. Kí O sì gba ìronúpìwàdà wa. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[129] Olúwa wa, gbé dìde nínú wọn Òjíṣẹ́ kan láààrin wọn, (ẹni tí) ó máa ké àwọn āyah Rẹ fún wọn, tí ó máa kọ́ wọn ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (sunnah), tí ó sì máa sọ wọ́n di ẹni mímọ́. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[130] Ta sì ni ó máa kọ ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sílẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gọ ẹ̀mí ara rẹ̀. A kúkú ti ṣà á lẹ́ṣà n’ílé ayé. Dájúdájú ó tún wà nínú àwọn ẹni rere ní ọ̀run

[131] (Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ mùsùlùmí.” Ó sọ pé: “Mo jẹ́ mùsùlùmí fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

[132] (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. (Ànábì) Ya‘ƙūb náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìkíní kejì sọ pé): "Ẹ̀yin ọmọ mi, dájúdájú Allāhu yan ẹ̀sìn náà fun yín. Nítorí náà, ẹ ò gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí

[133] Tàbí ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí nígbà tí ikú dé bá (Ànábì) Ya‘ƙūb? Nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ni ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn (ikú) mi?” Wọ́n sọ pé: "Àwa yó máa jọ́sìn fún Ọlọ́hun rẹ àti Ọlọ́hun àwọn bàbá rẹ, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo. Àwa sì ni mùsùlùmí (tí a juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un

[134] Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[135] Wọ́n wí pé: “Ẹ jẹ́ yẹhudi tàbí nasara kí ẹ mọ̀nà.” Sọ pé: "Rárá, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (lẹ̀sìn), olùdúró-déédé, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ

[136] Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí Wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un.”

[137] Nítorí náà, tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú irú ohun tí ẹ gbàgbọ́, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, wọ́n ti wà nínú ìyapa (òdodo). Allāhu sì máa tó ọ (níbi aburú) wọn. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[138] (Ẹ dúró ti) aró Allāhu. Ta sì l’ó dára ju Allāhu lọ ní aró! Àwa sì ni olùjọ́sìn fún Un

[139] Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yó jà wá níyàn nípa Allāhu ni?” Òun sì ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Àwa (mùsùlùmí) sì ni olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un

[140] Tàbí ẹ̀ ń wí pé: “Dájúdájú (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb, wọ́n jẹ́ yẹhudi tàbí nasara.” Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin l’ẹ nímọ̀ jùlọ (nípa wọn ni) tàbí Allāhu?” Ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó daṣọ bo ẹ̀rí ọ̀dọ̀ rẹ̀ (tí ó sọ̀kalẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu? Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[141] Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[142] Àwọn òmùgọ̀ nínú àwọn ènìyàn máa wí pé: “Kí ni ó mú wọn yí kúrò níbi Ƙiblah wọn tí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).”

[143] Báyẹn ni A ti ṣe yín ní ẹ̀ṣà ìjọ t’ó lóore jùlọ, nítorí kí ẹ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, àti nítorí kí Òjíṣẹ́ náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín. A kò sì ṣe Ƙiblah tí o wà lórí rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ibùkọjú-kírun bí kò ṣe pé nítorí kí Á lè ṣe àfihàn ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ yàtọ̀ sí ẹni tí ó máa yísẹ̀ padà. Dájúdájú ó lágbára àyàfi fún àwọn tí Allāhu tọ́ sọ́nà. Allāhu kò sì níí fi ìgbàgbọ́ yín ráre. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn

[144] A kúkú rí yíyí tí ò ń yí ojú rẹ sí sánmọ̀. Nítorí náà, A ó dojú rẹ kọ Ƙiblah kan tí o yọ́nú sí; nítorí náà, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram (ní Mọkkah). Ibikíbi tí ẹ bá tún wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀. Dájúdájú àwọn tí A fún ní Tírà kúkú mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni (àṣẹ Ƙiblah) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[145] Dájúdájú tí o bá fún àwọn tí A fún ní Tírà ní gbogbo āyah, wọn kò níí tẹ̀lé Ƙiblah rẹ. Ìwọ náà kò gbọdọ̀ tẹ̀lé Ƙiblah wọn. Apá kan wọn kò sì níí tẹ̀lé Ƙiblah apá kan. Dájúdájú tí o bá tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, dájúdájú nígbà náà ìwọ wà nínú àwọn alábòsí

[146] Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Dájúdájú àwọn ìjọ kan wà nínú wọn tí wọ́n kúkú ń fi òdodo pamọ́; wọ́n sì mọ̀

[147] Òdodo náà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì

[148] Ìkọ̀ọ̀kan (ìjọ ẹlẹ́sìn) l’ó ní ibùkọjúsí t’ó ń kọjú sí. Nítorí náà, ẹ yára gbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere. Ibikíbi tí ẹ bá wà, Allāhu yó mú gbogbo yín wá (ní Ọjọ́ Àjíǹde). Dájúdájú Alágbára ni Allāhu lórí gbogbo n̄ǹkan

[149] Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram, nítorí pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[150] Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram. Àti pé ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀, nítorí kí àwọn ènìyàn má baà ní àwíjàre lórí yín, àyàfi àwọn tí wọ́n ṣàbòsí nínú wọn (tí wọn kò yé jà yín níyàn). Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi, nítorí kí N̄g lè pé ìdẹ̀ra Mi fun yín àti nítorí kí ẹ lè mọ̀nà òòji rẹ̀ máa wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀ níkété tí òòrùn bá yẹ̀tàrí. Nígbà tí òpin ẹ̀bá òkè ìlà òòrùn ń jẹ́ àríwá-ìlà òòrùn (north-east) òpin ẹ̀bá ìsàlẹ̀ ìlà òòrùn sì ń jẹ́ gúsù-ìlà òòrùn (south-east). Nítorí náà

[151] gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan si yín láààrin ara yín, tí ó ń ké àwọn āyah Wa fun yín, tí ó ń sọ yín di ẹni mímọ́, tí ó ń kọ yín ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (sunnah), tí ó sì ń kọ yín ní ohun tí ẹ ò mọ̀ tẹ́lẹ̀

[152] Nítorí náà, ẹ rántí Mi, Mo máa rántí yín. Ẹ dúpẹ́ fún Mi, ẹ má ṣàì moore sí Mi

[153] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ fi sùúrù àti ìrun kíkí tọrọ oore (Allāhu). Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù

[154] Ẹ má ṣe pe àwọn tí wọ́n ń pa sí ojú-ogun ẹ̀sìn Allāhu ní òkú (ìyà), àmọ́ alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fura

[155] Dájúdájú A ó máa dan yín wò pẹ̀lú kiní kan látara ẹ̀rù, ebi, àdínkù nínú àwọn dúkìá, àwọn ẹ̀mí àti àwọn èso. Kí o sì fún àwọn onísùúrù ní ìró ìdùnnú

[156] Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n, wọ́n á sọ pé: “Dájúdájú Allāhu l’Ó ni àwa; dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwa yóò padà sí.”

[157] Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti ìkẹ́ yó máa bẹ fún láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùmọ̀nà

[158] Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ Hajj sí Ilé náà tàbí ó ṣe iṣẹ́ ‘Umrah, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un láti rìn yíká (láààrin àpáta) méjèèjì. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fínnú-fíndọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣegbọrẹ, dájúdájú Allāhu ni Amoore, Onímọ̀

[159] Dájúdájú àwọn t’ó ń daṣọ bo ohun tí A sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú àti ìmọ̀nà, lẹ́yìn tí A ti ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn sínú Tírà, àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ń ṣẹ́bi lé. Àwọn olùṣẹ́bi sì ń ṣẹ́bi lé wọn

[160] Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n sì ṣàfi hàn òdodo, nítorí náà àwọn wọ̀nyẹn ni Mo máa gba ìronúpìwàdà wọn. Èmi sì ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[161] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni ègún Allāhu, (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) ènìyàn pátápátá ń bẹ lórí wọn

[162] Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Nítorí náà, A ò níí gbé ìyà fúyẹ́ fún wọn. A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná)

[163] Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àyàfi Òun, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[164] Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán, àti àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn lórí omi pẹ̀lú (ríru) ohun t’ó ń ṣe àwọn ènìyàn ní àǹfààní, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní omi òjò láti sánmọ̀, tí Ó sì ń fi sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tí ó ti kú, àti (bí) Ó ṣe fọ́n gbogbo ẹranko ká sí orí ilẹ̀, àti ìyípadà atẹ́gùn àti ẹ̀ṣújò tí A tẹ̀ba láààrin sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè

[165] Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ (tó yẹ kí wọ́n ní sí) Allāhu. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì le jùlọ nínú ìfẹ́ sí

[166] (Rántí) nígbà tí àwọn tí wọ́n tẹ̀lé (nínú àìgbàgbọ́) máa yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ àwọn t’ó tẹ̀lé wọn; (nígbà tí) wọ́n bá fojú rí Ìyà, tí ohun t’ó so wọ́n pọ̀ sì já pátápátá

[167] Àwọn t’ó tẹ̀lé wọn yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú ìpadàwáyé lè wà fún wa ni, àwa ìbá yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wọn ni gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wa.” Báyẹn ni Allāhu yó ṣe fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n ní (iṣẹ́) òfò fún wọn. Wọn kò sì níí jáde kúrò nínú Iná

[168] Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jẹ nínú ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ (t’ó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti n̄ǹkan) dáadáa.Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín

[169] Ohun tí ó máa pa yín ní àṣẹ rẹ̀ ni (iṣẹ́) aburú, ìbàjẹ́ àti sísọ nípa Allāhu ohun tí ẹ ò nímọ̀ rẹ̀

[170] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé

[171] Àpèjúwe àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ dà bí àpèjúwe ẹni tí ó ń ké pe ohun tí kò lè gbọ́rọ̀ tayọ ìpè àti igbe (asán). Adití, ayaya, afọ́jú ni wọ́n; wọn kò sì níí ṣe làákàyè

[172] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fun yín, kí ẹ sì dúpẹ́ fún Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún

[173] Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fun yín ni òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti ohun tí wọ́n pe orúkọ mìíràn lé lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tí wọ́n bá fi ìnira (ebi) kan, yàtọ̀ sí ẹni t’ó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-àlà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[174] Dájúdájú àwọn t’ó ń daṣọ bo ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú Tírà, tí wọ́n sì ń tà á ní owó pọ́ọ́kú, àwọn wọ̀nyẹn kò jẹ kiní kan sínú wọn bí kò ṣe Iná. Allāhu kò sì níí bá wọn sọ̀rọ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[175] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà, (wọ́n tún fi) àforíjìn ra ìyà. Báwo ni wọn ṣe máa lè ṣèfaradà fún Iná ná

[176] Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé dájúdájú Allāhu sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àwọn t’ó sì yapa Tírà náà ti wà nínú ìyapà t’ó jìnnà (sí òdodo)

[177] Kì í ṣe ohun rere ni kí ẹ kọjú sí agbègbè ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, àmọ́ (olùṣe) rere ni ẹnikẹ́ni t’ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn mọlāika, Tírà (al-Ƙur’ān), àti àwọn Ànábì. Tòhun ti ìfẹ́ tí olùṣe-rere ní sí owó, ó tún ń fi owó náà tọrẹ fún àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù, onírìn-àjò (tí agara dá), àwọn atọrọjẹ àti (ìtúsílẹ̀) l’óko ẹrú. (Ẹni rere) yó máa kírun, yó sì máa yọ Zakāh. (Ẹni rere ni) àwọn t’ó ń mú àdéhùn wọn ṣe nígbà tí wọ́n bá ṣe àdéhùn àti àwọn onísùúrù nígbà àìríná-àìrílò, nígbà àìlera àti l’ójú ogun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe (iṣẹ́) òdodo. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùbẹ̀rù (Allāhu)

[178] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ẹ̀san gbígbà níbi ìpànìyàn ní ọ̀ran- anyàn fun yín. Olómìnira fún olómìnira, ẹrú fún ẹrú, obìnrin fún obìnrin. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ṣàmójú kúrò kiní kan fún láti ọ̀dọ̀ ọmọ ìyá (ẹni tí wọ́n pa, kí ẹni tí ó máa gba owó ẹ̀mí dípò ẹ̀mí) ṣe ohun rere tẹ̀lé (owó tí ó gbà, kí ẹni tí ó máa san’wó ẹ̀mí) san owó náà fún un ní ọ̀nà t’ó dára. Ìyẹn ni ìgbéfúyẹ́ àti àánú láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-àlà (òfin) lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un

[179] Ìsẹ̀mí wà fun yín nínú (òfin) ìgbẹ̀san ìpànìyàn, ẹ̀yin onílàákáyè, kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu)

[180] A ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fun yín, nígbà tí ikú bá dé bá ẹnì kan nínú yín, tí ó sì fi dúkìá sílẹ̀, pé kí ó sọ àsọọ́lẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára fún àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí. (Èyí jẹ́) ojúṣe fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[181] Ẹnikẹ́ni tí ó bá yí i padà lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ ọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yó sì wà lọ́rùn àwọn t’ó ń yí i padà. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[182] Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá bẹ̀rù àṣìṣe tàbí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó sọ àsọọ́lẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe láààrin (àwọn tí ogún tọ́ sí). Nítorí náà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[183] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fun yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu)

[184] (Ẹ gba ààwẹ̀ náà) fún àwọn ọjọ́ tí ó ní òǹkà. (Ṣùgbọ́n) ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ó wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) ní àwọn ọjọ́ mìíràn. Àti pé ìtánràn (ìyẹn) fífún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ l’ó di dandan fún àwọn t’ó máa fi ìnira gba ààwẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fínnúfíndọ̀ ṣe (àlékún) iṣẹ́ olóore, ó kúkú lóore jùlọ fún un. Àti pé kí ẹ gba ààwẹ̀ lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀

[185] Oṣù Rọmọdọ̄n èyí tí A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú rẹ̀ 1 (tí ó jẹ́) ìmọ̀nà, àwọn àlàyé pọ́nńbélé nípa ìmọ̀nà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà 2 fún àwọn ènìyàn; nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ìlú rẹ̀ nínú yín nínú oṣù náà, 3 kí ó gba ààwẹ̀ oṣù náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí tí ó bá wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) ní àwọn ọjọ́ mìíràn. Allāhu fẹ́ ìrọ̀rùn fun yín, kò sì fẹ́ ìnira fun yín. Ẹ pé òǹkà (ọjọ́ ààwẹ̀), kí ẹ sì gbé títóbi fún Allāhu nítorí pé Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ fún Un. àyè kan náà ni òkè ‘Arafah wà ṣùgbọ́n kò pọn dandan kí gbogbo ayé bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n ní ọjọ́ kan náà tí a bá fẹ́ kí ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n wa àti ìparí rẹ̀ máa jẹ́ ọjọ́ kan náà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pọn dandan bẹ́ẹ̀ nínú òfin ’Islām a bùkátà sí n̄ǹkan méjì gbòòrò. Ìkíní: aṣíwájú ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa jẹ́ onisunnah

[186] Nígbà tí àwọn ẹrúsìn Mi bá bi ọ léèrè nípa Mi, dájúdájú Èmi ni Olùsúnmọ́. Èmi yóò jẹ́pè àdúà aládùúà nígbà tí ó bá pè Mí. Kí wọ́n jẹ́’pè Mi (nípa ìtẹ̀lé àṣẹ Mi). Kí wọ́n sì gbà Mí gbọ́ nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà (gbígbà àdúà)

[187] Wọ́n ṣe alẹ́ ààwẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fun yín láti súnmọ́ àwọn ìyàwó yín; àwọn ni aṣọ yín, ẹ̀yin sì ni aṣọ wọn. Allāhu mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀ ń tan ara yín jẹ (nípa àìfẹ́ sun oorun ìfẹ́ ní alẹ́ ààwẹ̀). Ó ti gba ìronúpìwàdà yín, O sì ṣe àmójúkúrò fun yín. Ní báyìí, ẹ súnmọ́ wọn, kí ẹ sì wá ohun tí Allāhu kọ mọ yín (ní ọmọ). Ẹ jẹ, ẹ mu títí ẹ ó fi rí ìyàtọ̀ láààrin òwú funfun (ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀) àti òwú dúdú (ìyẹn, òkùnkùn òru) ní àfẹ̀mọ́júmọ́. Lẹ́yìn náà, ẹ parí ààwẹ̀ náà sí alẹ́ (nígbà tí òòrùn bá wọ̀). Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn nígbà tí ẹ bá ń kóra ró nínú àwọn mọ́sálásí. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-àlà (tí) Allāhu (gbékalẹ̀), ẹ má ṣe súnmọ́ ọn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Rẹ̀)

[188] Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ gbé dúkìá lọ bá àwọn adájọ́ (ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀) nítorí kí ẹ lè fi ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ìpín kan nínú dúkìá àwọn ènìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀

[189] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ìlétéṣù. Sọ pé: “Òhun ni (òǹkà) àkókò fún àwọn ènìyàn àti (òǹkà àkókò fún) iṣẹ́ Hajj. Kì í ṣe iṣẹ́ rere (fun yín) láti gba ẹ̀yìn-ìnkùlé wọnú ilé, ṣùgbọ́n (olùṣe) rere ni ẹni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà wọnú ilé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè

[190] Fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu, ẹ pa àwọn t’ó ń jà yín lógun. Kí ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-àlà. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn olùtayọ ẹnu-àlà

[191] Ẹ pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Kí ẹ sì lé wọn jáde kúrò níbi tí wọ́n ti le yín jáde. Ìfòòró le ju pípa lọ. Ẹ má ṣe bá wọn jà ní Mọ́sálásí Haram àfi ìgbà tí wọ́n bá ba yín jà nínú rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá ba yín jà, ẹ bá wọn jà. Báyẹn ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́

[192] Tí wọ́n bá sì jáwọ́ (nínú ìbọ̀rìṣà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[193] Ẹ gbógun tì wọ́n títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́. Ẹ̀sìn ’Islām yó sì wà (ní òmìnira) fún Allāhu. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú ìbọ̀rìṣà), kò sí ogun mọ́ àyàfi lórí àwọn alábòsí

[194] Oṣù ọ̀wọ̀ fún oṣù ọ̀wọ̀. Àwọn n̄ǹkan ọ̀wọ̀ sì ní (òfin) ìgbẹ̀san. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-àlà si yín, ẹ gb’ẹ̀san ìtayọ ẹnu-àlà lára rẹ̀ pẹ̀lú irú ohun tí ó fi tayọ ẹnu-àlà si yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[195] Ẹ náwó fún ogun ẹ̀sìn Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe fi ọwọ́ ara yín fa ìparun (nípa sísá fún ogun ẹ̀sìn). Ẹ ṣe rere. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere

[196] Ẹ ṣe àṣepé iṣẹ́ Hajj àti ‘Umrah fún Allāhu. Tí wọ́n bá sì se yín mọ́ ojú ọ̀nà, ẹ fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ fá irun orí yín títí di ìgbà tí ẹran ọrẹ náà yó fi dé àyè rẹ̀. Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí ìnira kan ń bẹ ní orí rẹ̀, ó máa fi ààwẹ̀ tàbí sàráà tàbí ẹran pípa ṣe ìtánràn (fún kíkánjú fá irun orí). Nígbà tí ẹ bá fọkànbalẹ̀ (nínú ewu), ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ‘Umrah àti Hajj nínú oṣù iṣẹ́ Hajj, ó máa fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹni tí kò bá rí (ẹran ọrẹ), kí ó gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta nínú (iṣẹ́) hajj, méje nígbà tí ẹ bá darí wálé. Ìyẹn ni (ààwẹ̀) mẹ́wàá t’ó pé. Ìyẹn wà fún ẹni tí kò sí ẹbí rẹ̀ ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà

[197] Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí A ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí oorun ìfẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ dídá àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj. Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe ní rere, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ẹ mú èsè ìrìn-àjò lọ́wọ́. Dájúdájú èsè ìrìn-àjò t’ó lóore jùlọ ni ìṣọ́ra (níbi èsè ẹlòmíìràn àti agbe ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ Hajj). Ẹ bẹ̀rù Mi, ẹ̀yin onílàákàyè

[198] Kò sí ìbáwí fun yín (níbi òwò ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ hajj) pé kí ẹ wá oore kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, tí ẹ bá ń darí bọ̀ láti ‘Arafah, ẹ ṣe ìrántí Allāhu ní àyè alápọ̀n-ọ́nlé (Muzdalifah). Ẹ ṣe ìrántí Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi ọ̀nà mọ̀ yín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹ wà nínú àwọn olùṣìnà

[199] Lẹ́yìn náà, ẹ dà lọ sí ibi tí àwọn ènìyàn bá dà lọ (nínú iṣẹ́ Hajj), kí ẹ sì tọrọ àforíjìn Allāhu. Dájúdájú, Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[200] Nígbà tí ẹ bá parí ìjọ́sìn (Hajj) yín, ẹ ṣèrántí Allāhu gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń ṣèrántí àwọn baba ńlá yín. Tàbí kí ìrántí náà lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń wí pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ayé.” Kò sì níí sí ìpín oore kan fún un ní ọ̀run

[201] Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni t’ó ń sọ pé: "Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná

[202] Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni ìpín oore nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́

[203] Ẹ ṣèrántí Allāhu láààrin àwọn ọjọ́ t’ó ní òǹkà. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kánjú (ṣe é) fún ọjọ́ méjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Ẹni tí ó bá kẹ́yìn (tí ó dúró di ọjọ́ kẹta), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un fún ẹni tí ó bá ṣọ́ra (fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[204] Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ̀ yó máa ṣe ọ́ ní kàyéfì nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, tí yó sì máa fi Allāhu jẹ́rìí sí ohun tí ń bẹ nínú ọkàn rẹ̀ (pé kò sí ìjà), oníjà t’ó le jùlọ sì ni

[205] Nígbà tí ó bá sì yísẹ̀ padà, ó máa ṣiṣẹ́ kiri lórí ilẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀, kí ó sì lè pa n̄ǹkan oko àti ẹran-ọ̀sìn run. Allāhu kò sì fẹ́ràn ìbàjẹ́

[206] Àti pé nígbà tí wọ̀n bá sọ fún un pé: “Bẹ̀rù Allāhu.” Ìgbéraga sì máa mú ún dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, iná Jahanamọ yóò tó o (ní ẹ̀san). Ibùgbé náà sì burú

[207] Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń ta ẹ̀mí ara rẹ̀ láti wá ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Aláàánú fún àwọn ẹrúsìn (Rẹ̀)

[208] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ kó s’ínú ẹ̀sìn ’Islām pátápátá. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ tẹ̀lé ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín

[209] Nítorí náà, tí ẹsẹ̀ yín bá yẹ̀ (kúrò nínú ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé ba yín, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[210] Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe pé kí Allāhu wá bá wọn nínú ibòji ẹ̀ṣújò, àwọn mọlāika náà (sì máa wá, nígbà náà) A ó sì yanjú ọ̀rọ̀ (ìṣírò iṣẹ́ ẹ̀dá)! Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí

[211] Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè pé: “Mélòó ni A ti fún wọn nínú āyah t’ó yanjú?” Ẹnikẹ́ni tí ó bá (fi àìgbàgbọ́) jìrọ̀ ìdẹ̀ra Allāhu lẹ́yìn tí ó dé bá a, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà

[212] Wọ́n ṣe ìṣẹ̀mí ayé ní ọ̀ṣọ́ (ẹ̀tàn) fún àwọn aláìgbàgbọ́. (Tí ayé bá sì yẹ wọ́n tán,) wọn yó máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn t’ó sì bẹ̀rù Allāhu máa wà l’ókè wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Àti pé Allāhu ń pèsè arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì la ìṣírò lọ

[213] Àwọn ènìyàn jẹ́ ìjọ kan ṣoṣọ (ẹlẹ́sìn ’Islām nípìlẹ̀). Allāhu sì gbé àwọn Ànábì dìde ní oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn pẹ̀lú òdodo nítorí kí Ó lè fi ṣe ìdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn nípa ohun tí wọ́n yapa ẹnu sí. Kò sì sí ẹni t’ó yapa ẹnu (sí ’Islām) àfi àwọn tí A fún ní Tírà, lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Nítorí náà, Allāhu tọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sọ́nà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọlọ̀tẹ̀1 yapa ẹnu sí nípa òdodo (’Islām). Allāhu yó máa tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà

[214] Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí irúfẹ́ (àdánwò) t’ó kan àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú yín kò tí ì kàn yín? Ìpọ́njú àti àìlera mú wọn. Wọ́n sì rí àmìwò tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Òjíṣẹ́ àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ fi sọ pé: “Ìgbà wo ni àrànṣe Allāhu máa dé sẹ́?” Kíyè sí i! Dájúdájú àrànṣe Allāhu súnmọ́

[215] Wọ́n ń bí ọ léèrè pé kí ni àwọn yó máa náwó sí. Sọ pé: "Ohun tí ẹ bá ná nínú ohun rere, kí ó máa jẹ́ ti àwọn òbí méjèèjì, àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe nínú ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀

[216] A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí, ohun ìkórira sì ni fun yín. Ó sì lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ oore fun yín. Ó sì tún lè jẹ́ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ aburú fún yín. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀

[217] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ogun jíjà nínú oṣù ọ̀wọ̀. Sọ pé: "Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ogun jíjà nínú rẹ̀. Àti pé ṣíṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò l’ójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ṣíṣe àìgbàgbọ́ nínú Allāhu, dídí àwọn mùsùlùmí lọ́wọ́ láti wọ inú Mọ́sálásí Haram àti lílé àwọn mùsùlùmí jáde kúrò nínú rẹ̀, (ìwọ̀nyí) tún tóbi jùlọ ní ẹ̀ṣẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Allāhu." Ìfòòró sì burú ju ìpànìyàn lọ. Wọn kò ní yéé gbógun tì yín títí wọn yó fi ṣẹ́ yín lórí kúrò nínú ẹ̀sìn yín, tí wọ́n bá lágbára (ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀). Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣẹ́rí kúrònínú ẹ̀sìn rẹ̀, tí ó sì kú sí ipò kèfèrí, nítorí náà àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[218] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn t’ó gbé ìlú (wọn) jù sílẹ̀ àti àwọn t’ó jagun fún ẹ̀sìn Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ń retí ìkẹ́ Allāhu. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[219] Wọ́n ń bí ọ léèrè nípa ọtí àti tẹ́tẹ́. Sọ pé: "Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá àti àwọn àǹfààní kan wà nínú méjèèjì fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì sì tóbi ju àǹfààní wọn lọ." Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè pé kí ni àwọn yó máa ná ní sàráà. Sọ pé: “Ohun tí ó bá ṣẹ́kù lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbọ́ bùkátà inú ilé tán (ni kí ẹ fi ṣe sàráà).” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fun yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀

[220] nípa ayé àti ọ̀run. Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn ọmọ òrukàn. Sọ pé: "Ṣíṣe àtúnṣe dúkìá wọn (láì níí dà á pọ̀ mọ́ dúkìá yín) l’ó dára jùlọ. Tí ẹ bá sì dà á pọ̀ mọ́ dúkìá yín, ọmọ ìyá yín (nínú ẹ̀sìn) kúkú ni wọ́n. Allāhu sì mọ òbìlẹ̀jẹ́ yàtọ̀ sí alátùn-únṣe. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (kí ẹ ya dúkìá wọn sí ọ̀tọ̀ nìkan ni) ìbá kó ìnira ba yín. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[221] Ẹ má fi àwọn abọ̀rìṣà lóbìnrin ṣaya títí wọn yó fi gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú ẹrúbìnrin onígbàgbọ́ òdodo lóore ju abọ̀rìṣà lóbìnrin, kódà kí abọ̀rìṣà lóbìnrin jọ yín lójú. Ẹ má sì fi onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin fún àwọn abọ̀rìṣà lọ́kùnrin títí wọn yó fi gbàgbọ́ ní òdodo. Ẹrúkùnrin onígbàgbọ́ òdodo lóore ju abọ̀rìṣà lọ́kùnrin, kódà kí abọ̀rìṣà lọ́kùnrin jọ yín lójú. Àwọn (abọ̀rìṣà) wọ̀nyẹn ń pèpè sínú Iná. Allāhu sì ń pèpè sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àforíjìn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ó sì ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[222] Wọ́n sì ń bi ọ́ léèrè nípa n̄ǹkan oṣù (obìnrin). Sọ pé: “Ìnira ni (sísúnmọ́ wọn lásìkò náà). Nítorí náà, ẹ yẹra fún àwọn obìnrin l’ásìkò n̄ǹkan oṣù. Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn (fún oorun ìfẹ́) títí wọn yó fi ṣe ìmọ́ra. Tí wọ́n bá sì ti ṣe ìmọ́ra, ẹ súnmọ́ wọn ní àyè tí Allāhu pa láṣẹ fun yín. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùronú-pìwàdà. Ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùmọ́ra

[223] Àwọn obìnrin yín, oko ni wọ́n fun yín. Ẹ lọ s’ínú oko yín bí ẹ bá ṣe fẹ́, kí ẹ sì ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ẹ̀mí ara yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ máa pàdé Rẹ̀. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú

[224] Ẹ má ṣe fi Allāhu ṣe ìkẹ́wọ́ fún ìbúra yín pé ẹ ò níí ṣe rere, ẹ ò níí ṣọ́ra (níbi ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ẹ ò sì níí ṣe àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[225] Allāhu kò níí fi ìbúra yín tí kò ti inú yín wá bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi ohun tí ó bá t’inú ọkàn yín wá bi yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà

[226] Ìkóraró fún oṣù mẹ́rin wà fún àwọn t’ó búra pé àwọn kò níí súnmọ́ obìnrin wọn. Tí wọ́n bá ṣẹ́rí padà (láààrin ìgbà náà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[227] Tí wọ́n bá sì pinnu ìkọ̀sílẹ̀, (kí wọ́n kọ̀ wọ́n sílẹ̀.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[228] Àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ máa kóra ró fún n̄ǹkan oṣù mẹ́ta. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti fi ohun tí Allāhu ṣ’ẹ̀dá (rẹ̀) s’ínú àpò-ọmọ wọn pamọ́, tí wọ́n bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àwọn ọkọ wọn ní ẹ̀tọ́ sí dídá wọn padà l’áààrin (àsìkò) yẹn, tí wọ́n bá gbèrò àtúnṣe. Àwọn ìyàwó ní ẹ̀tọ́ l’ọ́dọ̀ ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí àwọn ọkọ wọn ní l’ọ́dọ̀ wọn lọ́nà t’ó dára. Ipò àjùlọ tún wà fún àwọn ọkùnrin lórí wọn. Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[229] Ẹ̀ẹ̀ mejì ni ìkọ̀sílẹ̀. Nítorí náà, ẹ mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ fi wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú dáadáa. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fun yín láti gba kiní kan nínú ohun tí ẹ ti fún wọn àyàfi tí àwọn méjèèjì bá ń páyà pé àwọn kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-àlà (òfin) Allāhu (láààrin ara wọn). Nítorí náà, tí ẹ bá ń páyà pé àwọn méjèèjì kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-àlà (ofin) Allāhu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn nígbà náà nípa ohun tí obìnrin bá fi ṣèràpadà (ẹ̀mí ara rẹ̀) Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbé kalẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe tayọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbé kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí

[230] Nítorí náà, tí ọkọ bá kọ̀ ọ́ (ní ẹ̀ẹ̀ kẹta), obìnrin náà kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i mọ́ lẹ́yìn náà títí obìnrin náà yó fi fẹ́ ẹlòmíìràn. Tí ẹni náà bá tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì nígbà náà láti padà sí ọ̀dọ̀ ara wọn, tí àwọn méjèèjì bá ti lérò pé àwọn máa ṣọ́ àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀ (fún wọn), tí Ó ń ṣàlàyé rẹ̀ fún ìjọ t’ó nímọ̀

[231] Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí àsìkò (opó) wọn súnmọ́ kó parí, ẹ lè mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ (ní ìparí opó wọn) pẹ̀lú dáadáa. Ẹ má ṣe mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà ìnira láti lè tayọ ẹnu-àlà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn, ó kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹ má ṣe sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín àti ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fun yín nínú Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah Ànábì s.a.w.), tí Ó ń fi ṣe ìṣítí fun yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdáju Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[232] Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí wọ́n sì parí àsìkò (opó) wọn, ẹ má ṣe dí wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ ọkọ wọn, nígbà tí wọ́n bá jọ yọ́nú síra wọn (tí wọ́n sì gba) ọ̀nà tó dára . Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni nínú yín, t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Ó sì tún ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn yín) jùlọ. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀

[233] Àwọn abiyamọ yóò máa fún àwọn ọmọ wọn ní ọyàn mu fún ọdún méjì gbáko, fún ẹni tí ó bá fẹ́ parí (àsìkò) ìfọ́mọlọ́yàn. Ojúṣe ni fún ẹni tí wọ́n bímọ fún láti máa ṣe (ètò) ìjẹ-ìmu wọn àti aṣọ wọn ní ọ̀nà t’ó dára. Wọn kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Wọn kò níí kó ìnira bá abiyamọ nítorí ọmọ rẹ̀. Wọn kò sì níí kó ìnira bá ẹni tí wọ́n bímọ fún nítorí ọmọ rẹ̀. Irú (ojúṣe) yẹn tún ń bẹ fún olùjogún. Tí àwọn méjèèjì bá sì fẹ́ gba ọyàn l’ẹ́nu ọmọ pẹ̀lú ìpanupọ̀ àti àṣàrò àwọn méjèèjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì. Tí ẹ bá sì fẹ́ gba ẹni tí ó máa fún àwọn ọmọ yín lọ́yàn mu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín, tí ẹ bá ti fún wọn ní ohun tí ẹ fẹ́ fún wọn (ní owó-ọ̀yà) ní ọ̀nà t’ó dára. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[234] Àwọn tí ọkọ wọn kú nínú yín, tí wọ́n sì fi àwọn ìyàwó sílẹ̀, wọn yóò kóra ró fún oṣù mẹ́rin àti ọjọ́ mẹ́wàá. Nígbà tí wọ́n bá parí àsìkò (opó) wọn, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí wọ́n bá ṣe fúnra wọn (láti ní ọkọ mìíràn) ní ọ̀nà t’ó dára. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[235] Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ pẹ́sọ nínú ìbánisọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàbí tí ẹ fi pamọ́ sínú ẹ̀mí yín. Allāhu mọ̀ pé dájúdájù ẹ̀yin yó máa rántí wọn, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀, àyàfi pé kí ẹ máa sọ ọ̀rọ̀ dáadáa. Ẹ má ṣe pinnu ìta kókó yìgì títí àsìkò (opó) máa fi parí. Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Rẹ̀. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà

[236] Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín, tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, láì tí ì súnmọ́ wọn tàbí láì tí ì sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn ní pàtó. Kí ẹ sì fún wọn ní ẹ̀bùn (ìkọ̀sílẹ̀); kí olùgbòòrò (nínú arísìkí) fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀, kí tálíkà sì fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùṣe-rere

[237] Tí ẹ bá sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó súnmọ́ wọn, tí ẹ sì ti sọ òdiwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn, ìlàjì ohun tí ẹ ti ṣòdiwọ̀n rẹ̀ ní sọ̀daàkí (ni kí ẹ fún wọn), àfi tí wọ́n bá ṣàmójú kúrò (fún gbogbo rẹ̀, ìyẹn àwọn obìnrin) tàbí tí ẹni tí kókó yìgì ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀ bá ṣàmójú kúrò (fún gbogbo rẹ̀, ìyẹn àwọn ọkọ). Kí ẹ ṣàmójú kúrò ló súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Ẹ má ṣe gbàgbé oore àjùlọ ààrin yín. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[238] Ẹ ṣọ́ àwọn ìrun (wákàtí márààrún) àti (ní pàápàá jùlọ) ìrun ààrin. Kí ẹ sì dúró (kírun gẹ́gẹ́ bí) olùtẹríba fún Allāhu, láì níí sọ̀rọ̀ (mìíràn lórí ìrun)

[239] Ṣùgbọ́n tí ẹ bá ń bẹ̀rù (ọ̀tá l’ójú ogun ẹ̀sìn), ẹ kírun yín lórí ìrìn (ẹsẹ̀) tàbí lórí n̄ǹkan ìgùn. Nígbà tí ọkàn yín bá sì balẹ̀, ẹ kírun fún Allāhu gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀ (tẹ́lẹ̀) mọ̀ yín

[240] Àwọn tí wọ́n kú nínú yín, tí wọ́n sì fi àwọn ìyàwó sáyé lọ, kí wọ́n ṣe àsọọ́lẹ̀ ìjẹ-ìmu ọdún kan fún àwọn ìyàwó wọn, láì sì níí lé wọn jáde kúrò nínú ilé wọn. Tí wọ́n bá sì jáde (fúnra wọn lẹ́yìn ìjáde opó), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí wọ́n bá fi’ra wọn ṣe ní dáadáa (láti ní ọkọ mìíràn). Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[241] N̄ǹkan ìgbádùn ní ọ̀nà t’ó dára tún máa wà fún àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀sílẹ̀. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu

[242] Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè

[243] Ṣé o ò rí àwọn t’ó jáde láti inú ilé wọn lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún nítorí ìbẹ̀rù ikú! Allāhu sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kú.” Lẹ́yìn náà, Ó sọ wọ́n di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Olóore-àjùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò dúpẹ́ (fún Un)

[244] Ẹ jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[245] Ta ni ẹni tí ó máa yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára, kí Allāhu sì ṣe àdìpèlé (ẹ̀san) fún un ní àdìpèlé púpọ̀? Allāhu ń ká ọrọ̀ nílẹ̀, Ó sì ń tẹ́ ẹ sílẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí

[246] Ṣé o ò rí àwọn aṣíwájú nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, lẹ́yìn (ìgbà Ànábì) Mūsā? Nígbà tí wọ́n wí fún Ànábì tiwọn pé: “Yan ọba kan fún wa, kí á lọ jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu.” Ó sọ pé: “Ṣebí ó ṣe é ṣe pé tí Wọ́n bá ṣe ogun jíjà ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí tán ẹ ò kúkú níí jagun?” Wọ́n wí pé: "Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ láti jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu? Wọ́n kúkú ti lé àwa àti àwọn ọmọ wa jáde kúrò nínú ilé wa!" Àmọ́ nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí tán, wọ́n pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí

[247] Ànábì wọn sọ fún wọn pé: “Dájúdájú Allāhu ti gbé Tọ̄lūt dìde fun yín ní ọba.” Wọ́n wí pé: “Báwo ni ó ṣe lè jẹ ọba lé wa lórí nígbà tí ó jẹ́ pé àwa ní ẹ̀tọ́ sí ipò ọba jù ú lọ? Kò sì ní owó púpọ̀ lọ́wọ́?” Ó sọ pé: "Dájúdájú Allāhu ṣà á lẹ́ṣà le yín lórí. Ó sì fún un ní àlékún púpọ̀ nínú ìmọ̀ àti okun ara. Allāhu ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ìjọba Rẹ̀. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀

[248] Ànábì wọn tún sọ fún wọn pé: "Dájúdájú àmì ìjọba rẹ̀ ni pé, àpótí yóò wá ba yín. N̄ǹkan ìfàyàbalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti ohun t’ó ṣẹ́kù nínú ohun tí àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā àti ènìyàn (Ànábì) Hārūn fi sílẹ̀ ń bẹ nínú àpótí náà. Àwọn mọlāika máa rù ú wá (ba yín). Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fun yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[249] Nígbà tí Tọ̄lūt jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu máa fi odò kan dan yín wò. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú rẹ̀, kì í ṣe ẹni mi. Ẹni tí kò bá tọ́ ọ wò dájúdájú òun ni ẹni mi, àyàfi ẹni tí ó bá bu ìwọ̀n ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ kan mu.” (Ṣùgbọ́n) wọ́n mu nínú rẹ̀ àfi díẹ̀ nínú wọn. Nígbà tí òun àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ sọdá odò náà, wọ́n sọ pé: “Kò sí agbára kan fún wa lónìí tí a lè fi k’ojú Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” Àwọn t’ó mọ̀ pé dájúdájú àwọn máa pàdé Allāhu, wọ́n sọ pé: "Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ (ogun) kékeré t’ó ti ṣẹ́gun ìjọ (ogun) púpọ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù

[250] Nígbà tí wọ́n jáde sí Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sọ pé: "Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu, fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ ṣinṣin, kí O sì ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́

[251] Wọ́n sì ṣẹ́gun wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Dāwūd sì pa Jālūt. Allāhu sì fún un ní ìjọba àti ọgbọ́n. Ó tún fi ìmọ̀ mọ̀ ọ́n nínú ohun tí Ó bá fẹ́. Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, orí ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí gbogbo ẹ̀dá

[252] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Àti pé dájúdájú ìwọ wà lára àwọn Òjíṣẹ́

[253] Àwọn Òjíṣẹ́ wọ̀nyẹn, A ṣoore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan. Ó ń bẹ nínú wọn, ẹni tí Allāhu bá sọ̀rọ̀ (tààrà). Ó sì ṣe àgbéga àwọn ipò fún apá kan wọn. A fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. A tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) ràn án lọ́wọ́. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, àwọn t’ó wá lẹ́yìn wọn ìbá tí bára wọn jà lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n yapa ẹnu (si ẹ̀sìn ’Islām). Ó ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (tí ó jẹ́ mùsùlùmí). Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ (tí ó di nasara). Àti pé tí Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí bá’ra wọn jà, ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́

[254] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ná nínú ohun tí A ṣe ní arísìkí fun yín ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé. Kò níí sí títà-rírà kan nínú rẹ̀. Kò níí sí olólùfẹ́ kan, kò sì níí sí ìṣìpẹ̀ kan (fún àwọn aláìgbàgbọ́). Àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn sì ni alábòsí

[255] Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi

[256] Kò sí ìjẹnípá nínú ẹ̀sìn. Ìmọ̀nà ti fojú hàn kúrò nínú ìṣìnà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí àwọn òrìṣà, tí ó sì ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ó kúkú ti dìmọ́ okùn t’ó fọkàn balẹ̀ jùlọ, tí kò níí já. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[257] Allāhu ni Alárànṣe àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn òrìṣà ni aláfẹ̀yìntì wọn. Àwọn òrìṣà ń mú wọn jáde kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ wá sínú àwọn òkùnkùn. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀

[258] Ṣé o ò rí ẹni t’ó bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jiyàn nípa Olúwa rẹ̀, nítorí pé Allāhu fún un ní ìjọba? Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” Ó wí pé: “Èmi náà ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Mo sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Dájúdájú Allāhu ń mú òòrùn wá láti ibùyọ. Mú un wa nígbà náà láti ibùwọ̀." Wọ́n sì pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ lẹnu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[259] Tàbí bí ẹni tí ó kọjá nínú ìlú kan nígbà tí ó ti tú tòrùlé-tòrùlé rẹ̀. Ó sọ pé: “Báwo ni Allāhu yó ṣe sọ èyí di alààyè lẹ́yìn ikú rẹ̀!” Allāhu sì sọ ọ́ di òkú fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Lẹ́yìn náà, Ó gbé e dìde. Ó sọ pé: “Ìgbà wo ni o ti wà níbí?” Ó sọ pé: “Mo wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìlàjì ọjọ́.” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, o wà níbí fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Wo oúnjẹ rẹ àti omi rẹ, kò yí padà. Tún wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí Á lè fi ọ́ ṣe àmì kan fún àwọn ènìyàn. Sì tún wo eegun náà bí A ó ṣe tò wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, (wo) bí A ó ṣe da ẹran bò ó lára. Nígbà tí ó fojú hàn sí i kedere (bẹ́ẹ̀), ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”

[260] Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, fi hàn mí bí Ìwọ yó ṣe sọ àwọn òkú di alààyè." (Allāhu) sọ pé: “Ṣé ìwọ kò gbàgbọ́ ni?” Ó sọ pé: “Rárá, ṣùgbọ́n kí ọkàn mi lè balẹ̀ ni”. (Allāhu) sọ pé: "Mú mẹ́rin nínú àwọn ẹyẹ, kí o so wọ́n mọ́lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ (kí o pa wọ́n, kí o sì gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn). Lẹ́yìn náà, fi ìpín nínú wọn sórí àpáta kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pè wọ́n. Wọ́n máa sáré wá bá ọ. Kí o sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[261] Àpèjúwe àwọn t’ó ń ná owó wọn fún ẹ̀sìn Allāhu dà bí àpèjúwe kóró èso kan tí ó hu ṣiri méje jáde, tí ọgọ́rùn-ún kóró sì wà lára ṣiri kọ̀ọ̀kan. Allāhu yó ṣe àdìpèlé fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀

[262] Àwọn t’ó ń ná owó wọn fún ẹ̀sìn Allāhu, tí wọn kò sì fi ìrègún àti ìpalára tẹ̀lé ohun tí wọ́n ná, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Ìbẹ̀rù kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́

[263] Ọ̀rọ̀ rere àti àforíjìn lóore jùlọ sí sàráà tí ìpalára tẹ̀lé. Allāhu sì ni Ọlọ́rọ̀, Aláfaradà

[264] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi ìrègún àti ìpalára ba àwọn sàráà yín jẹ́, bí ẹni tí ń ná owó rẹ̀ pẹ̀lú ṣekárími, kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àpèjúwe rẹ̀ dà bí àpèjúwe àpáta kan tí erùpẹ̀ ń bẹ lórí rẹ̀. Òjò ńlá rọ̀ sí i, ó sì kó erùpẹ̀ kúrò lórí rẹ̀ pátápátá. Wọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́

[265] Àpèjúwe àwọn t’ó ń ná owó wọn láti wá ìyọ́nú Allāhu àti (nítorí) ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú ẹ̀mí wọn, ó dà bí àpèjúwe ọgbà oko t’ó wà lórí ilẹ̀ gíga kan, tí òjò ńlá rọ̀ sí, tí àwọn èso rẹ̀ sì yọ jáde ní ìlọ́po méjì. Tí òjò ńlá kò bá sì rọ̀ sí i, ìrì ń ṣẹ̀ sí i. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe

[266] Ǹjẹ́ ẹnì kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí kí òun ní ọgbà oko dàbínù àti àjàrà, tí àwọn odò ń ṣàn ní abẹ́ rẹ̀, tí oríṣiríṣi èso tún wà fún un nínú rẹ̀, kí ogbó dé bá a, ó sì ní àwọn ọmọ wẹẹrẹ tí kò lágbara (iṣẹ́ oko ṣíṣe), kí atẹ́gùn líle tí iná ń bẹ nínú rẹ̀ kọlu oko náà, kí ó sì jóná? Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah náà fun yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀

[267] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ná nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí ẹ ṣe níṣẹ́ àti nínú àwọn n̄ǹkan tí A mú jáde fun yín láti inú ilẹ̀. Ẹ má ṣe gbèrò láti ná nínú èyí tí kò dára. Ẹ̀yin náà kò níí gbà á àfi kí ẹ dijú gbà a. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn

[268] Èṣù ń fi òṣì dẹ́rù bà yín, ó sì ń pa yín ní àṣẹ ìbàjẹ́ ṣíṣe. Allāhu sì ń ṣe àdéhùn àforíjìn àti oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ fun yín. Allāhu ní Olùgbààyè, Onímọ̀

[269] Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní òye ìjìnlẹ̀. Ẹni tí A bá sì fún ní òye ìjìnlẹ̀, A kúkú ti fún un ní oore púpọ̀. Ẹnì kan kò níí lo ìrántí àfi àwọn onílàákàyè

[270] Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ìnáwó tàbí (ohunkóhun) tí ẹ bá jẹ́ ní ẹ̀jẹ́, dájúdájú Allāhu mọ̀ ọ́n. Kò sì níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún àwọn alábòsí

[271] Tí ẹ bá ṣàfi hàn àwọn sàráà, ó kúkú dára. Tí ẹ bá sì fi pamọ́, tí ẹ lọ́ fún àwọn aláìní, ó sì dára jùlọ fun yín. Allāhu sì máa pa àwọn ìwà àìdáa yin rẹ́ fun yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[272] Ìmọ̀nà wọn kò sí lọ́rùn rẹ, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ẹni tí Ó bá fẹ́ mọ̀nà. Ohunkóhun tí ẹ bá ń ná ní ohun rere, fún ẹ̀mí ara yín ni. Ẹ ò sì níí náwó àfi láti fi wá ojú rere Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ná ní ohun rere, A ó san yín ní ẹ̀san (rẹ̀) ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí si yín

[273] (Ẹ tọrẹ) fún àwọn aláìní tí wọ́n sé (ara wọn mọ́nú mọ́sálásí Ànábì nítorí kí wọ́n lè máa jagun) fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò sì lágbára lílọ-bíbọ̀ lórí ilẹ̀ (fún òkòwò ṣíṣe). Ẹni tí kò mọ̀ wọ́n máa kà wọ́n kún ọlọ́rọ̀ látara àìṣagbe. O máa mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Wọn kò níí tọrọ n̄ǹkan lọ́wọ́ ènìyàn lemọ́lemọ́. Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀

[274] Àwọn t’ó ń ná owó wọn ní òru àti ní ọ̀sán, ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpayà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́

[275] Àwọn t’ó ń jẹ èlé kò níí dìde (nínú sàréè) àfi bí ẹni tí Èṣù fọwọ́ bà tí ń ta gẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́ yó ṣe dìde. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n wí pé: “Òwò ṣíṣe dà bí òwò èlé.” Allāhu sì ṣe òwò ṣíṣe ní ẹ̀tọ́, Ó sì ṣe òwò èlé ní èèwọ̀. Ẹnikẹ́ni tí wáàsí bá dé bá láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, tí ó sì jáwọ́, tirẹ̀ ni èyí t’ó ṣíwájú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì padà (síbi òwò èlé), àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀

[276] Allāhu máa run òwò èlé. Ó sì máa bù sí àwọn ọrẹ. Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀

[277] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n kírun, tí wọ́n sì yọ Zakāh, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpayà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́

[278] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì fi ohun t’ó ṣẹ́kù nínú èlé sílẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[279] Tí ẹ ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lọ mọ̀ pé ogun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (ń bọ̀ wá ba yín). Tí ẹ bá sì ronú pìwàdà, tiyín ni ojú-owó yín. Ẹ ò níí ṣàbòsí (sí wọn). Wọn kò sì níí ṣàbòsí si yín

[280] Tí (onígbèsè) bá jẹ́ ẹni tí ara ń ni, ẹ wò ó níran di àsìkò ìdẹ̀ra. Àti pé kí ẹ fị ṣe sàráà (fún un) lóore jùlọ fun yín, tí ẹ bá mọ̀

[281] Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí wọ́n máa da yín padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ (nípa) ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[282] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń ṣe kátà-kárà ní àwìn fún gbèdéke àkókò kan, ẹ ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Kí akọ̀wé ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ láààrin yín ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Kí akọ̀wé má ṣe kọ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi mọ̀ ọ́n. Nítorí náà. kí ó ṣe àkọsílẹ̀. Kí ẹni tí ẹ̀tọ́ wà lọ́rùn rẹ̀ pè é fún un. Kí ó bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Kò má ṣe dín kiní kan kù nínú rẹ̀. Tí ẹni tí ẹ̀tọ́ wà lọ́rùn rẹ̀ bá jẹ́ aláìlóye tàbí aláìsàn, tàbí kò lè pè é (fúnra rẹ̀), kí alámòjúútó rẹ̀ bá a pè é ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Kí ẹ pe ẹlẹ́rìí méjì nínú àwọn ọkùnrin yín láti jẹ́rìí sí i. Tí kò bá sí ọkùnrin méjì, kí ẹ wá ọkùnrin kan àti obìnrin méjì nínú àwọn ẹlẹ́rìí tí ẹ yọ́nú sí; nítorí pé tí ọ̀kan nínú àwọn obìnrin méjèèjì bá gbàgbé, ọ̀kan yó sì rán ìkejì létí. Kí àwọn ẹlẹ́rìí má ṣe kọ̀ tí wọ́n bá pè wọ́n (láti jẹ́rìí). Ẹ má ṣe káàárẹ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, ó kéré ni tàbí ó tóbi, títí di àsìkò ìsangbèsè rẹ̀. Ìyẹn ni déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì gbé ìjẹ́rìí dúró jùlọ. Ó tún fi súnmọ́ jùlọ pé ẹ̀yin kò fi níí ṣeyèméjì. Àfi tí ó bá jẹ́ kátà-kárà ojú ẹsẹ̀ tí ẹ̀ ń ṣe ní àtọwọ́dọ́wọ́ láààrin ara yín, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín tí ẹ ò bá ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ẹ wá ẹlẹ́rìí sẹ́ nígbà tí ẹ bá ń ṣe kátà-kárà (ọjà àwìn). Wọn kò sì níí kó ìnira bá akọ̀wé àti ẹlẹ́rìí. Tí ẹ bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, dájúdájú ìbàjẹ́ l’ẹ ṣe. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Allāhu yó sì máa fi ìmọ̀ mọ̀ yín. Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[283] Àti pé tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò, tí ẹ̀yin kò sì rí akọ̀wé, ẹ gba ohun ìdógò. (Ṣùgbọ́n) tí apá kan yín bá fi ọkàn tán apá kan, kí ẹni tí wọ́n fi ọkàn tán dá ohun tí wọ́n fi ọkàn tán an lé lórí padà, kí ó sì bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Ẹ má ṣe fi ẹ̀rí pamọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi pamọ́, dájúdájú ọkàn rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe

[284] Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Tí ẹ bá ṣàfi hàn ohun t’ó wà nínú ẹ̀mí yín, tàbí ẹ fi pamọ́, Allāhu yó ṣírò rẹ̀ fun yín (tí ẹ bá ṣe é níṣẹ́). Lẹ́yìn náà, Ó máa foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[285] Òjíṣẹ́ náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.”

[286] Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. (Ẹ̀san) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (rere) ń bẹ fún un. (Ìyà) ohun tí ó ṣe ní’ṣẹ́ (ibi) ń bẹ fún un pẹ̀lú. Olúwa wa, má ṣe mú wa tí a bá gbàgbéra tàbí (tí) a bá ṣàṣìṣe. Olúwa wa, má ṣe di ẹrù t’ó wúwo lé wa lórí, gẹ́gẹ́ bí O ṣe dì í ru àwọn t’ó ṣíwájú wa. Olúwa wa, má ṣe dìrù wá ohun tí kò sí agbára rẹ̀ fún wa. Ṣàmójú kúrò fún wa, foríjìn wá, kí O sì ṣàánú wa. Ìwọ ni Aláfẹ̀yìntì wa. Nítorí náà, ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́

Ìdílé Imran

Surah 3

[1] ’Alif lām mīm

[2] Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá

[3] Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó sì sọ Taorāh àti ’Injīl kalẹ̀

[4] ní ìṣaájú. Ìmọ̀nà sì ni fún àwọn ènìyàn.1 Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀.2 Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà t’ó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san

[5] Dájúdájú Allāhu, kò sí kiní kan t’ó pamọ́ fún Un nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀

[6] Òun ni Ẹni tí Ó ń yàwòrán yín sínú àpòlùkẹ́ bí Ó ṣe fẹ́. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára Ọlọ́gbọ́n

[7] Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè. kò sí āyah tàbí hadith kan tí ó ní pọ́n-na tí ìtakora wọn wá wọ ipò “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀” (at-ta‘ārudu al-haƙīƙiy). Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’

[8] Olúwa wa, má ṣe yí wa lọ́kàn padà lẹ́yìn tí O ti tọ́ wa sọ́nà. Ta wá lọ́rẹ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, dájúdájú Ìwọ ni Ọlọ́rẹ

[9] Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O máa kó àwọn ènìyàn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kì í yẹ àdéhùn

[10] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná

[11] (Ìṣesí wọn) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Allāhu sì le níbi ìyà

[12] Sọ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Wọ́n máa ṣẹ́gun yín. Wọ́n sì máa ko yín jọ sínú iná Jahanamọ. Ibùgbé náà sì burú

[13] Àmì kúkú wà fun yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn). Ìjọ kan ń jà fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Ìkejì sì jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ìjọ kejì ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú. Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùrìran

[14] Wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn ènìyàn; ìfẹ́ ìgbádùn lára àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin, àwọn owó wúrà àti fàdákà púpọ̀ àti àwọn ẹṣin tí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́, àwọn ẹran-ọ̀sìn àti (n̄ǹkan) oko. Ìyẹn ni n̄ǹkan ìgbáyé-gbádùn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ rere wà

[15] Sọ pé: “Ṣé kí n̄g sọ n̄ǹkan t’ó dára ju ìyẹn lọ fun yín?” Àwọn t’ó bá bẹ̀rù (Allāhu), àwọn Ọgbà tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn ìyàwó mímọ́ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu (tún ń bẹ fún wọn). Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn

[16] àwọn t’ó ń sọ pé: "Olúwa wa, dájúdájú àwa gbàgbọ́. Nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá. Kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná

[17] (Ọgbà Ìdẹ̀ra yẹn wà fún) àwọn onísùúrù, àwọn olódodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, àwọn olùnáwó-fẹ́sìn àti àwọn olùtọrọ-àforíjìn ní àsìkò sààrì

[18] Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[19] Dájúdájú ẹ̀sìn t’ó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. Àwọn tí A fún ní Tírà (àwọn yẹhudi àti kristiẹni) kò yapa ẹnu (sí ẹ̀sìn náà) àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Ẹni t’ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́

[20] Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ pé: “Èmi àti ẹni tí ó tẹ̀lé mi juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu.” Kí o sì sọ fún àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) pé: “Ṣé ẹ máa gba ’Islām?” Tí wọ́n bá gba ’Islām, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì kẹ̀yìn (sí ’Islām), iṣẹ́-jíjẹ́ nìkan ni ojúṣe tìrẹ. Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn

[21] Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́, tí wọ́n tún ń pa àwọn ènìyàn tí ń pàṣẹ ṣíṣe ẹ̀tọ́, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[22] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ilé ayé àti ní ọ̀run. Wọn kò sì níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́

[23] Ṣé o ò rí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú Tírà, tí À ń pè síbi Tírà Allāhu, kí ó lè ṣe ìdájọ́ láààrin wọn, lẹ́yìn náà tí ìjọ kan nínú wọn ń pẹ̀yìn dà, tí wọ́n sì ń gbúnrí

[24] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n wí pé: “Iná kò lè jó wa tayọ àwọn ọjọ́ t’ó lóǹkà.” Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì tàn wọ́n jẹ nínú ẹ̀sìn wọn

[25] Nítorí náà, báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí A bá kó wọn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀? Àti pé A máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[26] Sọ pé: “Allāhu, Olùkápá ìjọba, Ò ń fi ìjọba fún ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń gba ìjọba lọ́wọ́ ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń buyì kún ẹni tí O bá fẹ́. O sì ń tàbùkù ẹni tí O bá fẹ́. Ọwọ́ Rẹ ni oore wà. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbárá lórí gbogbo n̄ǹkan

[27] Ò ń mú òru wọnú ọ̀sán. Ò ń mú ọ̀sán wọnú òru. Ò ń mú alààyè jáde lára òkú. Ò ń mú òkú jáde lára alààyè. O sì ń ṣe arísìkí fún ẹni tí O bá fẹ́ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.”

[28] Kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo má ṣe mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Àfi (tí ẹ bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ lórí ahọ́n) láti fi ṣọ́ra fún wọn ní ti wíwá ààbò (fún ìgbàgbọ́ yín). Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fun yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[29] Sọ pé: “Tí ẹ bá fi ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín pamọ́ tàbí ẹ fi hàn, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ó sì mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[30] Ní ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò rí ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ rere níwájú (rẹ̀) àti ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ ibi, ó máa fẹ́ kí àkókò t’ó jìnnà wà láààrin òun àti iṣẹ́ ibi rẹ̀. Allāhu sì ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fun yín. Allāhu sì ni Aláàánú àwọn olùjọ́sìn

[31] Sọ pé: “Tí ẹ̀yin bá nífẹ̀ẹ́ Allāhu, ẹ tẹ̀lé mi, Allāhu máa nífẹ̀ẹ́ yín, Ó sì máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[32] Sọ pé: “Ẹ tẹ̀lé (ti) Allāhu àti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́

[33] Dájúdájú Allāhu ṣa Ādam, Nūh, ará ilé ’Ibrọ̄hīm àti ará ilé ‘Imrọ̄n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn)

[34] Wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ; apá kan wọn wá láti ara apá kan. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[35] (Ẹ rántí) nígbà tí aya ‘Imrọ̄n sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi fi ohun tí ń bẹ nínú mi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọ (pé) mo máa yà á sọ́tọ̀ (fún ẹ̀sìn Rẹ). Nítorí náà, gbà á lọ́wọ́ mi, dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[36] Nígbà tí ó bí i, ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo bí i ní obìnrin - Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ó bí – ọkùnrin kò sì dà bí obìnrin. Dájúdájú èmi sọ ọ́ ní Mọryam. Àti pé dájúdájú mò ń fi Ọ́ wá ààbò fún òun àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ lọ́dọ̀ Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.”

[37] Olúwa rẹ̀ sì gba àdúà náà ní gbígbà dáadáa. Ó sì mú ọmọ náà dàgbà ní ìdàgbà dáadáa. Ó sì fi Zakariyyā ṣe alágbàtọ́ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí Zakariyyā bá wọlé tọ̀ ọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, ó máa bá èsè (èso) lọ́dọ̀ rẹ̀. (Zakariyyā á) sọ pé: “Mọryam, báwo ni èyí ṣe jẹ́ tìrẹ?” (Mọryam á) sọ pé: "Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń ṣe arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀

[38] Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: "Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́ àdúà

[39] Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): "Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu. (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò sì níí súnmọ́ obìnrin. (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere

[40] (Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?” (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.”

[41] (Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé ìwọ kò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta àyàfi títọ́ka (sí n̄ǹkan). Rántí Olúwa rẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ (fún Un) ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtù

[42] (Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó fọ̀ ọ́ mọ́. Ó sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé (àsìkò tìrẹ)

[43] Mọryam, tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ. Forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì dáwọ́ tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun)

[44] Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò. Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfan̄fà (lórí rẹ̀)

[45] (Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: "Mọryam, dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa dídá ẹ̀dá kan pẹ̀lú) ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Abiyì ni ní ayé àti ní ọ̀run. Ó sì wà lára alásùn-únmọ́ (Allāhu). nínú āyah ti āli ‘Imrọ̄n Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa bí àwọn mọlā’ikah ṣe wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbi ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àwọn mọlāika t’ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà ju ẹyọ kan lọ. Ìdí nìyí tí “mọlā’ikah” fi jẹ́ ọ̀pọ̀ nínú āyah yẹn. Àmọ́ nínú āyah ti Mọryam

[46] Ó máa bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà t’ó bá dàgbà. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere

[47] (Mọryam) sọ pé: “Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí.” Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀

[48] (Allāhu) yóò fún un ní ìmọ̀ ìkọ̀wé, ìjìnlẹ̀ òye, Taorāh àti ’Injīl

[49] (Ó sì jẹ́) Òjíṣẹ́ (tí A rán níṣẹ́) sí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (Ó sì máa sọ fún wọn pé) "Dájúdájú èmi ti mú àmì kan wá fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Dájúdájú èmi yóò mọ n̄ǹkan fun yín láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ. Èmi yóò fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀. Ó sì máa di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò ṣe ìwòsàn fún afọ́jú àti adẹ́tẹ̀, mo sì máa sọ òkú di alààyè pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ sínú ilé yín. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fun yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[50] Mo sì ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú mi nínú Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe ní ẹ̀tọ́ fun yín apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fun yín. Mo ti mú àmì kan wá fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[51] Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà

[52] Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: “Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: "Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá

[53] Olúwa wa, a gbàgbọ́ nínú ohun tí O sọ̀kalẹ̀. A sì tẹ̀lé Òjíṣẹ́. Nítorí náà, kọ wá mọ́ àwọn olùjẹ́rìí

[54] Wọ́n déte, Allāhu sì déte. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte

[55] Wafāt/wafāh sì túmọ̀ sí ""ƙọbd"" gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n 3:55 ati sūrah al-Mọ̄’dah ẹlẹ́sìn ’Islām ni àwọn t’ó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àti ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ọ̀wọ́ àwọn t’ó tẹ̀lé e lójú ayé rẹ̀ mùsùlùmí ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pera wọn bẹ́ẹ̀ nínú sūrah yìí

[56] Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò jẹ wọ́n níyà líle ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn

[57] Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní kíkún. Allāhu kò sì fẹ́ràn àwọn alábòsí

[58] Ìyẹn ni À ń ké fún ọ nínú àwọn āyah àti ìrántí tí ó kún fún ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān)

[59] Dájúdájú irú ‘Īsā lọ́dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam; (Allāhu) dá a láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀. ẹrú Ọlọ́hun àti Ànábì Ọlọ́hun. Àmọ́ sísọ tí àwọn kristiẹni sọ Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di olúwa wọn olùgbàlà wọn

[60] Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, má ṣe wà nínú àwọn oníyèméjì

[61] Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jà ọ́ níyàn nípa rẹ̀ lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kí o sọ pé: “Ẹ wá! Kí á pe àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn obìnrin wa àti àwọn obìnrin yín àti àwa àti ẹ̀yin náà. Lẹ́yìn náà, kí á ṣe àdúà taratara, kí á sì tọrọ ègún Allāhu lé àwọn òpùrọ́ lórí.”

[62] Dájúdájú èyí, òhun ni ìtàn òdodo. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[63] Tí wọ́n bá sì pẹ̀yìn dà (níbi òdodo náà), dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́

[64] Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlu-l-kitāb, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan t’ó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu.” Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: “Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa.”

[65] Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi jiyàn nípa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm? A kò sì sọ at-Taorāh àti al-’Injīl kalẹ̀ bí kò ṣe lẹ́yìn rẹ̀, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni

[66] Ẹ̀yin ni ìwọ̀nyí tí ẹ̀ ń jiyàn nípa ohun tí ẹ nímọ̀ nípa rẹ̀! Kí ni ó tún ń mu yín jiyàn nípa ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀? Allāhu nímọ̀. Ẹ̀yin kò sì nímọ̀

[67] (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm kì í ṣe yẹhudi, kì í ṣe kristiẹni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ olùdúró-déédé, mùsùlùmí. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ

[68] Dájúdájú àwọn ènìyàn t’ó súnmọ́ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jùlọ ni àwọn t’ó tẹ̀lé e àti Ànábì yìí (Ànábì Muhammad s.a.w.) àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Allāhu ni Alátìlẹ́yìn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[69] Igun kan nínú àwọn ahlul-kitāb fẹ́ láti ṣì yín lọ́nà. Wọn kò lè ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àfi ara wọn, wọn kò sì fura

[70] Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ẹ sì ń jẹ́rìí (sí òdodo rẹ̀)

[71] Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì ń fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo)

[72] Igun kan nínú àwọn ahlul-kitāb wí pé: “Ẹ lọ gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kí ẹ sì takò ó níparí rẹ̀, bóyá àwọn mùsùlùmí (kan) máa ṣẹ́rí padà (sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn ’Islām)

[73] (Wọ́n tún wí pé:) “Ẹ má gbàgbọ́ àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀sìn yín.” Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà (’Islām) ni ìmọ̀nà ti Allāhu.” (Wọ́n tún wí pé:) “(Ẹ má gbàgbọ́) pé wọ́n fún ẹnì kan ní irú ohun tí Wọ́n fun yín tàbí pé wọn yóò takò yín (tí wọn yó sì jàre yín) lọ́dọ̀ Olúwa yín.” Sọ pé: “Dájúdájú oore àjùlọ wà ní ọwọ́ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.”

[74] (Allāhu) ń ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu ni Olóore ńlá

[75] Ó ń bẹ nínú àwọn ahlul-kitāb, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ owó, ó máa dá a padà fún ọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú owó dinar kan (owó kékeré), kò níí dá a padà fún ọ àyàfi tí o bá dógò tì í lọ́rùn. Ìyẹn nítorí pé wọ́n wí pé: “Wọn kò lè fí ọ̀nà kan kan bá wa wí nítorí àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà.” Ńṣe ni wọ́n ń pa irọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀

[76] Rárá (A máa bá wọn wí). Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[77] Dájúdájú àwọn t’ó ń ta májẹ̀mu Allāhu àti ìbúra wọn ní owó kékeré, àwọn wọ̀nyẹn, kò níí sí ìpín oore fún wọn ní Ọjọ́ Ìkẹyìn. Allāhu kò níí bá wọn sọ̀rọ̀, kò sì níí ṣíjú wò wọ́n ní Ọjọ́ Àjíǹde. Kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀) Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì ń bẹ fún wọn

[78] Dájúdájú ìjọ kan ń bẹ nínú wọn t’ó ń fi ahọ́n wọn yí tírà (Allāhu) padà, nítorí kí ẹ lè lérò pé lára tírà ló wà, kò sì sí lára tírà. Wọ́n sì ń wí pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kò sì wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀

[79] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan nígbà tí Allāhu bá fún un ní tírà, ìjìnlẹ̀ òye àti ipò Ànábì, lẹ́yìn náà kí ó máa sọ fún àwọn ènìyàn pé, "ẹ jẹ́ ẹrúsìn fún mi lẹ́yìn Allāhu." Ṣùgbọ́n (ó máa sọ pé) "ẹ jẹ́ olùjọ́sìn fún Olúwa (kí ẹ sì máa fi ẹ̀kọ́ Rẹ̀ kọ́ àwọn ènìyàn) nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tírà àti nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ ẹ̀kọ́ (nípa ẹ̀sìn)

[80] (Ànábì kan) kò sì níí pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ sọ àwọn mọlāika àti àwọn Ànábì di olúwa. Ṣé ó máa pa yín ní àṣẹ ṣíṣe àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ́ mùsùlùmí ni

[81] (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábì pé: “(Ẹ lo) èyí tí Mo bá fun yín nínú Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad s.a.w.) yóò dé ba yín; ó máa fi èyí t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́.” (Allāhu) sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?” Wọ́n sọ pé: “A gbà.” (Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí

[82] Nítorí náà, ẹni tí ó bá kẹ̀yìn sí (Ànábì Muhammad s.a.w.) lẹ́yìn (àdéhùn) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́

[83] Ṣé ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Allāhu ni wọ́n ń wá ni? Nígbà tí ó jẹ́ pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Wọ́n máa dá wọn padà sí

[84] Sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa pẹ̀lú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”

[85] Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò

[86] Báwo ni Allāhu yó ṣe fi ọ̀nà mọ ìjọ kan t’ó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn? Wọ́n sì jẹ́rìí pé dájúdájú Òjíṣẹ́ náà, òdodo ni. Àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú sì ti dé bá wọn. Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[87] Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn ni pé, dájúdájú ègún Allāhu àti (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) gbogbo àwọn ènìyàn ń bẹ lórí wọn

[88] Olùṣegbére ni wọ́n nínú ègún. Nítorí náà, A ò níí gbé ìyà fúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná)

[89] Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe, nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[90] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n lékún ní àìgbàgbọ́, A ò níí gba ìronúpìwàdà wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni olùṣìnà

[91] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn

[92] Ọwọ́ yin kò lè ba oore àyàfi tí ẹ bá ń ná nínú ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ná, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀

[93] Gbogbo oúnjẹ ló jẹ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl àyàfi èyí tí ’Isrọ̄’īl bá ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ṣíwájú kí A tó sọ at-Taorāh kalẹ̀. Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú at-Taorāh wá, kí ẹ sì kà á síta tí ẹ̀yin bá jẹ́ olódodo.”

[94] Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí

[95] Sọ pé: "Allāhu sọ òdodo. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ

[96] Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah . (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá

[97] Àwọn àmì t’ó yanjú wà nínú rẹ̀; ibùdúró (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú rẹ̀ ti di ẹni ìfàyàbalẹ̀. Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, t’ó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́,dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá

[98] Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu? Allāhu sì ni Arínú-róde ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[99] Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ fi ń ṣẹ́rí ẹni t’ó gbàgbọ́ lódodo kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ẹ sì ń fẹ́ kó wọ́, ẹ sì jẹ́rìí (sí òdodo ’Islām)? Allāhu kì í ṣe Onígbàgbé nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[100] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé apá kan nínú àwọn tí A fún ní tírà, wọ́n máa da yín padà lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo yín sí ipò aláìgbàgbọ́

[101] Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà

[102] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bẹ̀rù Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ wà ní ipò mùsùlùmí

[103] Ẹ dúró ṣinṣin ti okùn Allāhu (’Islām) ní àpapọ̀, ẹ má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí ẹ sì rántí ìkẹ́ Allāhu tí ń bẹ lórí yín (pé) nígbà tí ẹ jẹ́ ọ̀tá (ara yín nígbà àìmọ̀kan), Ó pa ọkàn yín pọ̀ mọ́ra wọn (pẹ̀lú ’Islām), ẹ sì di ọmọ ìyá pẹ̀lú ìkẹ́ Rẹ̀; àti (nígbà tí) ẹ wà létí ọ̀gbun Iná, Ó gbà yín là kúrò nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà (’Islām)

[104] Kí ó máa bẹ nínú yín, ìjọ kan tí yóò máa pèpè síbi ohun t’ó lóore jùlọ, wọn yóò máa pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì máa kọ ohun burúkú. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè

[105] Ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó sọra wọn di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì yapa ẹnu (sí ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn àlàyé t’ó yanjú ti dé bá wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà ńlá ń bẹ fún

[106] Ní ọjọ́ tí àwọn ojú kan yóò funfun (ìmọ́lẹ̀). Àwọn ojú kan yó sì dúdú. Ní ti àwọn tí ojú wọn dúdú, (A ó bi wọ́n pé:) "Ṣé ẹ ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín ni?" Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ṣàì gbàgbọ́

[107] Ní ti àwọn tí ojú wọn funfun (ìmọ́lẹ̀), nínú ìkẹ́ Allāhu ni wọn yóò wà. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[108] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí kan sí gbogbo ẹ̀dá

[109] Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí

[110] Ẹ jẹ́ ìjọ t’ó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn , ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́

[111] Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fun yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́

[112] Àbùkù yóò máa bá wọn níbikíbi tí ọwọ́ àwọn (mùsùlùmí) bá ti bá wọn àfi (tí wọ́n bá ń bẹ) pẹ̀lú ààbò láti ọ̀dọ̀ Allāhu (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gba ’Islām) àti ààbò láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gbà láti máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām). Wọ́n ṣẹ́rí padà pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì kó òṣì bá wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu àlà

[113] (Àwọn ahlul-kitāb) kò rí bákan náà. Ìjọ kan t’ó dúró déédé wà nínú àwọn ahlul-kitāb, tí ń ké àwọn āyah Allāhu ní àkókò òru, tí wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ (lórí ìrun)

[114] Wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n sì ń yara níbi àwọn iṣẹ́ olóoore. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn ẹni rere

[115] Ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe ní iṣẹ́ rere, A ò níí jẹ́ kí wọ́n pàdánù ẹ̀san rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[116] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan níbi ìyà lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[117] Àpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn t’ó ṣe àbòsí s’órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí

[118] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú aláfinúhàn kan yàtọ̀ sí ara yín. Wọn kò níí géwọ́ aburú kúrú fun yín. Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ó máa kó ìnira ba yín. Ìkórira kúkú ti fojú hàn láti ẹnu wọn. Ohun tí ó sì pamọ́ sínú ọkàn wọn tóbi jùlọ. A ti ṣàlàyé àwọn āyah fun yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onílàákàyè

[119] Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn kò sì nífẹ̀ẹ́ yín. Ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú àwọn tírà, gbogbo rẹ̀ (pátápátá). Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé yín, wọ́n á wí pé: “Àwa gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku àwọn nìkan, wọn yóò máa deyín mọ́ ìka lórí yín ní ti ìbínú. Sọ pé: “Ẹ kú pẹ̀lú ìbínú yín.” Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá

[120] Tí dáadáa kan bá kàn yín, ó máa kó ìbànújẹ́ bà wọn. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ si yín, wọ́n máa dunnú sí i. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì ṣọ́ra (fún wọn), ète wọn kò níí kó ìnira kan kan ba yín. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[121] (Rántí) nígbà tí o jí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ara ilé rẹ ní ìdájí kùtùkùtù, tí ò sì ń fi àyè ibùjagun han àwọn onígbàgbọ́ òdodo, Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[122] (Rántí) nígbà tí ìjọ méjì nínú yín fẹ́ ṣojo. Allāhu sì ni Aláfẹ̀yìntì àwọn méjèèjì. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé

[123] Allāhu kúkú fun yín ní ìṣẹ́gun ní ogun Badr, nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìlágbára. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)

[124] Rántí nígbà tí ò ń sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo pé: “Ṣé kò níí to yín tí Olúwa yín bá ṣe ìrànlọ́wọ́ fun yín pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú àwọn mọlāika, tí Wọ́n máa sọ̀kalẹ̀?”

[125] Rárá (ó máa tó wa.). Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrú, tí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, tí àwọn (ọ̀tá) bá dé ba yín lójijì, Olúwa yín yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún máàrún nínú àwọn mọlāika pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ lára wọn

[126] Allāhu kò ṣe é lásán bí kò ṣe kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú fun yín àtí nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe lórí ọ̀tá (láti ibì kan kan) bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[127] (Allāhu ṣe àrànṣe náà fun yín) nítorí kí Ó lè gé apá kan dànù nínú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tàbí nítorí kí Ó lè dójú tì wọ́n, tí wọ́n sì máa padà wálé lófo

[128] Kò sí ohun t’ó kàn ọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà. Yálà (Allāhu) máa gba ìronúpìwàdà wọn tàbí Ó máa jẹ wọ́n níyà; dájúdájú alábòsí ni wọ́n

[129] Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ó ń foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́, Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[130] Ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe jẹ èlé, àdìpèlé lórí àdìpèlé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè

[131] Kí ẹ sì ṣọ́ra fún Iná tí Wọ́n ti pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[132] Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín

[133] Ẹ yára wá àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí ìbú rẹ̀ tó àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Wọ́n pa lésè sílẹ̀ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[134] Àwọn t’ó ń ná owó wọn nígbà ìdẹ̀ra àti nígbà ìnira, àwọn tí ń gbé ìbínú mì, àwọn alámòjúúkúrò fún àwọn ènìyàn níbi àṣìṣe; Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere

[135] Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni)

[136] Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn ni àforíjìn àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san olùṣe-iṣẹ́ rere sì dára

[137] Àwọn orípa kan kúkú ti lọ ṣíwájú yín. Nítorí náà, ẹ rin ilẹ̀ lọ, kí ẹ wòye sí bí ìgbẹ̀yìn àwọn t’ó pe òdodo nírọ́ ṣe rí

[138] Èyí ni àlàyé fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti wáàsí sì ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[139] Ẹ má ṣe kọ́lẹ, ẹ sì má ṣe banújẹ́; ẹ̀yin l’ẹ máa lékè tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[140] Tí ìpalára kan bá kàn yín, irú ìpalára bẹ́ẹ̀ kúkú ti kan ìjọ kèfèrí. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, À ń yí i po láààrin àwọn ènìyàn ni. Àti pé nítorí kí Allāhu lè ṣe àfihàn àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè (tẹ́wọ́) gba àwọn t’ó máa kú fún Un nínú yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí

[141] Àti pé (ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè ṣàfọ̀mọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè run àwọn aláìgbàgbọ́

[142] Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí Allāhu kò tí ì ṣàfi hàn àwọn t’ó máa jagun (ẹ̀sìn) nínú yín, tí kò sì tí ì ṣàfi hàn àwọn onísùúrù

[143] Dájúdájú ẹ ti ń fẹ́ ikú (ogun ẹ̀sìn) ṣíwájú kí ẹ tó pàdé rẹ̀. Ẹ kúkú ti rí i (báyìí), ẹ sì ń wòran

[144] Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀. Ṣé tí ó bá kú tàbí tí wọ́n bá pa á, ẹ máa pẹ̀yìn dà (sẹ́sìn)? Ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìn dà (sẹ́sìn) kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Allāhu yó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere. awọ ẹran òkúǹbete tí wọ́n pa lósè kì í ṣe èèwọ̀ fún lílò fún ọ̀ṣọ́ ilé tàbí ọ̀ṣọ́ ara. Irú awọ ẹran òkúǹbete tí wọ́n pa lósè bẹ́ẹ̀ sì di ẹ̀tọ́ láti fi ṣe bàtà bẹ́lítì

[145] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹ̀mí kan láti kú àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ikú jẹ́) àkọsílẹ̀ onígbèdéke. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ayé, A máa fún un ní ayé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ọ̀run, A máa fún un ní ọ̀run. A ó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere

[146] Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí wọ́n ti jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọmọ-ẹ̀yìn (wọn). Wọn kò ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ojú ogun ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò kọ́lẹ, wọn kò sì jura wọn sílẹ̀ fún ọ̀tá ẹ̀sìn. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn onísùúrù

[147] Kò sì sí ohun kan tí wọ́n sọ tayọ pé wọ́n sọ pé: "Olúwa wa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣejù wa nínú ọ̀rọ̀ wa jìn wá, mú ẹsẹ̀ wa dúró ṣinṣin, kí O sì ṣe àrànṣe fún wa lórí ìjọ aláìgbàgbọ́

[148] Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ẹ̀san ayé àti dáadáa ẹ̀san ọ̀run. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe rere

[149] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa yi yín lẹ́sẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Nígbà náà, ẹ máa padà di ẹni òfò (sínú àìgbàgbọ́)

[150] Allāhu sì ni Alárànṣe yín. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn alárànṣe

[151] A máa fi ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sínú ọkàn àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́, èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún. Iná sì ni ibùgbé wọn; ilé àwọn alábòsí sì burú

[152] Dájúdájú Allāhu ti mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fun yín nígbà tí ẹ̀ ń pa wọ́n pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀, títí di ìgbà tí ẹ fi ṣojo, tí ẹ sì ń jiyàn sí ọ̀rọ̀. Ẹ sì yapa (àṣẹ Ànábì) lẹ́yìn tí Allāhu fi ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí hàn yín. - Ó wà nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ayé, ó sì ń bẹ nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ọ̀run. - Lẹ́yìn náà, (Allāhu) yí ojú yín kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, kí Ó lè dan yín wò. Ó sì ti ṣàmójú kúrò fun yín; Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[153] (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gùnkè sá lọ, tí ẹ̀yin kò sì bojú wo ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn, Òjíṣẹ́ sì ń pè yín láti ẹ̀yìn yín. Nítorí náà, (Allāhu) fi ìbànújẹ́ (pípa tí àwọn ọ̀ṣẹbọ pa àwọn kan láààrin yín) san yín ní ẹ̀san ìbànújẹ́ (tí ẹ fi kan Ànábì nípasẹ̀ àìtẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ lójú ogun ’Uhd. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ẹ má baà banújẹ́ lórí ohun tí ó bọ́ fun yín àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[154] Lẹ́yìn náà, Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ kalẹ̀ fun yín lẹ́yìn ìbànújẹ́; òògbé ta igun kan lọ nínú yín. Igun kan tí ẹ̀mí ara wọn sì ti kó ìrònú bá, tí wọ́n sì ń ní èròkérò sí Allāhu lọ́nà àìtọ́, èròkérò ìgbà àìmọ̀kan, wọ́n sì ń wí pé: “Ǹjẹ́ a ní àṣẹ kan (tí a lè mú wá) lórí ọ̀rọ̀ náà bí!” Sọ pé: “Dájúdájú gbogbo àṣẹ ń jẹ́ ti Allāhu.” Wọ́n ń fi pamọ́ sínú ọkàn wọn ohun tí wọn kò lè ṣàfi hàn rẹ̀ fún ọ. Wọ́n ń wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé a ní àṣẹ kan lórí ọ̀rọ̀ náà ni, wọn ìbá tí pa wá síbí." Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ wà nínú ilé yín, àwọn tí A ti kọ àkọọ́lè pípa sí ibùjàgun wọn mọ ìbá kúkú jáde lọ síbẹ̀.” (Ogun yìí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè gbìdánwò ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà yín àti nítorí kí Ó lè ṣàfọ̀mọ́ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[155] Dájúdájú àwọn t’ó pẹ̀yìn dà nínú yín ní ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé, dájúdájú Èṣù l’ó yẹ̀ wọ́n lẹ́sẹ̀ nítorí apá kan ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì kúkú ti ṣàmójú kúrò fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà

[156] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ìyá wọn, nígbà tí wọ́n ń rìn kiri ní orí ilẹ̀ tàbí (nígbà) tí wọ́n ń jagun, pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wa ni, wọn ìbá tí kú, àti pé wọn ìbá tí pa wọ́n.” (Wọ́n wí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi ìyẹn ṣe àbámọ̀ sínú ọkàn wọn. Allāhu l’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[157] Dájúdájú tí wọ́n bá pa yín s’ójú ogun ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ kú (sínú ilé), dájúdájú àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Allāhu lóore ju ohun tí ẹ̀ ń kójọ (nílé ayé)

[158] Dájúdájú tí ẹ bá kú (sínú ilé) tàbí wọ́n pa yín (s’ójú ogun ẹ̀sìn), dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni wọn máa ko yín jọ sí

[159] Ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó kúkú rọ̀ ọ́ fún wọn; tí ó bá jẹ́ pé o jẹ́ ẹni burúkú, ọlọ́kàn líle, wọn ìbá ti túká kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ṣàmójú kúrò fún wọn, bá wọn tọrọ àforíjìn, kí o sì bá wọn jíròrò lórí ọ̀rọ̀. Tí o bá sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan), kí o gbáralé Allāhu. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùgbáralé E

[160] Tí Allāhu bá ṣe àrànṣe fun yín, kò sí ẹni tí ó máa borí yín. Tí Ó bá sì yẹpẹrẹ yín, ta sì ni ẹni tí ó máa ṣe àrànṣe fun yín lẹ́yìn Rẹ̀? Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé

[161] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti jí mú nínú ọrọ̀ ogun ṣíwájú kí wọ́n tó pín in. Ẹnikẹ́ní tí ó bá jí ọrọ̀ ogun mú ṣíwájú kí wọ́n tó pín in, ó máa dá ohun tí ó jí mú nínú ọrọ̀ ogun náà padà ní Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn

[162] Ṣé ẹni tí ó (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu dà bí ẹni tí ó padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, ibùgbé rẹ̀ sì ni iná Jahanamọ? Ìkángun náà sì burú

[163] (Èkínní kejì èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná ni) wọ́n ní ipò (ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[164] Allāhu kúkú ti ṣe oore fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí Ó fi lè gbé Òjíṣẹ́ kan dìde sí wọn láààrin ara wọn. (Òjíṣẹ́ náà) ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà (al-Ƙur’ān) àti ìjìnlẹ̀ òye (sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[165] Ṣé gbogbo ìgbà tí àdánwò kan bá kàn yín, tí ẹ sì ti fi méjì irú rẹ̀ (kan àwọn kèfèrí), ni ẹ̀yin yóò máa sọ pé: “Ọ̀nà wo ni èyí gbà ṣẹlẹ̀ sí wa?” Sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ ara yín.” Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[166] Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ tí ikọ̀ ogun méjèèjì pàdé (ṣẹlẹ̀) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni

[167] (Ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn t’ó ṣọ̀bẹ-ṣèlu (nínú àwọn mùsùlùmí). (Àwọn onígbàgbọ́ òdodo) sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí á lọ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ wá dáàbò bo ẹ̀mí ara yín.” Wọ́n wí pé: “Àwa ìbá mọ ogun-ún jà àwa ìbá tẹ̀lé yín.” Wọ́n súnmọ́ àìgbàgbọ́ ní ọjọ́ yẹn ju ìgbàgbọ́ lọ. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́

[168] Àwọn t’ó sọ nípa àwọn ọmọ ìyá wọn (t’ó kú s’ójú ogun ẹ̀sìn) pé – tí àwọn sì jòkóò kalẹ̀ sílé (ní tiwọn), "Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n tẹ̀lé tiwa ni, wọn ìbá tí pa wọ́n." Sọ pé: “Ẹ yẹkú dànù fún ẹ̀mí yín tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

[169] Ẹ má ṣe lérò pé òkú (ìyà) ni àwọn tí wọ́n pa s’ójú ogun ẹ̀sìn Allāhu, àmọ́ alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n. Wọ́n sì ń pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn

[170] Wọ́n ń dunnú nítorí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀. Wọ́n sì ń yọ̀ fún àwọn tí kò tí ì pàdé wọn nínú àwọn tí wọ́n fi sílẹ̀ pé: “Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.”

[171] Wọ́n ń bá wọn yọ̀ fún ìkẹ́ àti oore-àjùlọ (tí ń dúró dè wọ́n) lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn onígbàgbọ́ òdodo ráre

[172] (Àwọn ni) àwọn t’ó jẹ́pè Allāhu àti Òjíṣẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti f’ara gbọgbẹ́. Ẹ̀san ńlá wà fún àwọn t’ó ṣe rere, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu) nínú wọn

[173] (Àwọn ni) àwọn tí àwọn ènìyàn wí fún pé: “Wọ́n mà ti kóra jọ dè yín, nítorí náà ẹ bẹ̀rù wọn.” (Èyí) lékún ìgbàgbọ́ òdodo wọn. Wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó fún wa. Ó sì dára ni Alámòójútó.”

[174] Nítorí náà, wọ́n padà délé pẹ̀lú ìkẹ́ àti oore-àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Aburú kan kò sì kàn wọ́n. Àti pé wọ́n (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Olóore ńlá

[175] Dájúdájú ìyẹn ni Èṣù, tí ń fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dẹ́rù bà yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn. Kí ẹ sì bẹ̀rù Mi tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[176] Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń sáré kó sínú àìgbàgbọ́ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Dájúdájú wọn kò lè kó ìnira kan bá Allāhu. Allāhu kò fẹ́ kí ìpín kan nínú oore wà fún wọn ní ọ̀run (ni); ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn

[177] Dájúdájú àwọn t’ó fi ìgbàgbọ́ òdodo ra àìgbàgbọ́, wọn kò lè kó ìnira kan bá Allāhu. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[178] Kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé bí A ṣe ń lọ́ra fún wọn jẹ́ oore fún wọn. A kàn ń lọ́ra fún wọn nítorí kí wọ́n lè lékún nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún wọn

[179] Allāhu kò níí gbé àwọn onígbàgbọ́ òdodo jù sílẹ̀ lórí ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀ (níbi àìmọ onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí ṣọ̀bẹ-ṣèlu) títí Ó máa fi ya ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára ẹni dáadáa. Allāhu kò sì níí fi ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ mọ̀ yín, ṣùgbọ́n Allāhu yóò ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Tí ẹ bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), ẹ̀san ńlá yó sì wà fun yín

[180] Kí àwọn t’ó ń ṣahun pẹ̀lú ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀ má ṣe lérò pé oore ni fún wọn. Rárá, aburú ni fún wọn. A ó fí ohun tí wọ́n fi ṣahun dì wọ́n lọ́rùn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[181] Allāhu kúkú ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú aláìní ni Allāhu, àwa sì ni ọlọ́rọ̀.” A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n wí àti pípa tí wọ́n pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. A sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”

[182] Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì síwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀)

[183] Àwọn t’ó wí pé: "Dájúdájú Allāhu ṣàdéhùn fún wa pé a ò gbọdọ̀ gba Òjíṣẹ́ kan gbọ́ títí ó máa fí mú sàráà kan wá fún wa tí iná (àtọ̀runwá) yóò fi lánu." Sọ pé: "Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín ṣíwájú mi pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí to yanjú àti èyí tí ẹ wí (yìí), nítorí kí ni ẹ fi pa wọ́n tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[184] Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ ní òpùrọ́. Wọ́n wá pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ìpín-ìpín Tírà àti Tírà t’ó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn

[185] Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A ó sì san yín ní ẹ̀san yín ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí A bá mú jìnnà tefé sí Iná, tí A sì mú wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó kúkú ti jèrè. Kí sì ni ìgbésí ayé bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn

[186] Dájúdájú A ó máa dan yín wò nínú dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìpalára láti ọ̀dọ̀ àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ t’ó pọn dandan

[187] (Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn àwọn tí A fún ní tírà pé ẹ gbọ́dọ̀ ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn, ẹ ò sì gbọdọ̀ fi pamọ́. Wọ́n sì jù ú sẹ́yìn lẹ́yìn wọn. Wọ́n sì tà á ní owó kékeré. Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń tà mà sì burú (níyà)

[188] Ẹ má ṣe lérò pé àwọn t’ó ń dunnú sí ohun tí wọ́n ṣe (ní àìdáa máa là nínú ìyà). Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí kí àwọn (ènìyàn) máa yìn wọ́n fún ohun tí wọn kò ṣe (níṣẹ́ rere). Nítorí náà, ẹ má ṣe rò wọ́n ro ìgbàlà níbi Ìyà. Ìyà ẹlẹ́ta eléro sì wà fún wọn

[189] Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[190] Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán; (àmì wà nínú wọn) fún àwọn onílàákàyè

[191] Àwọn t’ó ń rántí Allāhu ní ìnàró, ìjókòó àti ní ìdùbúlẹ̀; tí wọ́n ń ronú sí ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (wọ́n sì ń sọ pé:) "Olúwa wa, Ìwọ kò ṣẹ̀dàá èyí pẹ̀lú irọ́. Mímọ́ ni fún Ọ. Nítorí náà, ṣọ́ wa níbi ìyà Iná

[192] Olúwa wa, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí O bá mú wọ inú Iná, O ti dójú tì í. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún àwọn alábòsí

[193] Olúwa wa, dájúdájú àwa gbọ́ olùpèpè kan t’ó ń pe (ìpè) sí ibi ìgbàgbọ́ pé: "Ẹ gba Olúwa yín gbọ́.” A sì gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá, kí O sì pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́, kí O sì pa wá pẹ̀lú àwọn ẹni rere

[194] Olúwa wa, fún wa ní ohun tí O ṣàdéhùn rẹ̀ fún wa lórí (ahọ́n) àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ. Má sì ṣe dójú tì wá ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Ìwọ kì í yapa àdéhùn

[195] Olúwa wọn sì jẹ́pè wọn pé: “Dájúdájú Èmi kò níí fi iṣẹ́ oníṣẹ́ kan nínú yín ráre; ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ara kan náà ni yín (níbi ẹ̀san). Nítorí náà, àwọn t’ó gbé (ìlú wọn) jù sílẹ̀, tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn, tí wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n nítorí ẹ̀sìn Mi, wọ́n jagun ẹ̀sìn, wọ́n sì pa wọ́n. Dájúdájú Èmi yóò bá wọn pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Èmi yó sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ẹ̀san dáadáa wà

[196] Má ṣe gba ẹ̀tàn pẹ̀lú ìgbòkè-gbodò àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìlú

[197] Ìgbádùn díẹ̀ (lè wà fún wọn), lẹ́yìn náà iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ibùgbé náà sì burú

[198] Ṣùgbọ́n àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ibùdésí kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì lóore jùlọ fún àwọn ẹni rere

[199] Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn ahlul-kitāb ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fun yín àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn; wọ́n ń páyà Allāhu, wọn kì í ta àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu ní owó kékeré. Àwọn wọ̀nyẹn ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́

[200] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣe sùúrù, ẹ pàrọwà sùúrù, ẹ ṣọ́ bodè ìlú yín (láti lè dènà àwọn ọmọ-ogun ọ̀tá ẹ̀sìn). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè

Àwọn Obìnrin

Surah 4

[1] Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan (ìyẹn, Ànábì Ādam). Ó sì ṣẹ̀dá aya rẹ̀ (Hawā’) láti ara rẹ̀. Ó fọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ara àwọn méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀ ń fi bẹ ara yín. (Ẹ ṣọ́) okùn-ìbí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí yín

[2] Ẹ fún àwọn ọmọ òrukàn ní dúkìá wọn. Ẹ má ṣe fi n̄ǹkan burúkú pààrọ̀ n̄ǹkan dáadáa. Ẹ sì má ṣe jẹ dúkìá wọn mọ́ dúkìá yín; dájúdájú ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá

[3] Tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé nípa (fífẹ́) ọmọ òrukàn, ẹ fẹ́ ẹni t’ó lẹ́tọ̀ọ́ si yín nínú àwọn obìnrin; méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé, (ẹ fẹ́) ẹyọ kan tàbí ẹrúbìnrin yín. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ pé ẹ ò níí ṣàbòsí

[4] Ẹ fún àwọn obìnrin ní sọ̀daàkí wọn ní tọkàn-tọkàn. Tí wọ́n bá sì fi inú dídùn yọ̀ǹda kiní kan fun yín nínú rẹ̀, ẹ jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti ìgbádùn

[5] Ẹ má ṣe kó dúkìá yín tí Allāhu fí ṣe gbẹ́mìíró fun yín lé àwọn aláìlóye lọ́wọ́. Ẹ pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn nínú rẹ̀, kí ẹ sì raṣọ fún wọn. Kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn

[6] Ẹ máa ṣàgbéyẹ̀wò (òye) àwọn ọmọ òrukàn títí wọn yóò fi tó ìgbéyàwó ṣe. Tí ẹ bá sì ti rí òye lára wọn, kí ẹ dá dúkìá wọn padà fún wọn. Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ dúkìá wọn ní ìjẹ àpà àti ìjẹkújẹ kí wọ́n tó dàgbà. Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí ó mójú kúrò (níbẹ̀). Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìní, kí ó jẹ nínú rẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára. Nítorí náà, tí ẹ bá fẹ́ dá dúkìá wọn padà fún wọn, ẹ pe àwọn ẹlẹ́rìí sí wọn. Allāhu sì tó ní Olùṣírò

[7] Àwọn ọkùnrin ní ìpín nínú ohun tí òbí méjèèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Àti pé àwọn obìnrin náà ní ìpín nínú ohun tí òbí méjéèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Nínú ohun t’ó kéré nínú rẹ̀ tàbí t’ó pọ̀; (ó jẹ́) ìpín tí wọ́n ti pín (fún wọn)

[8] Nígbà tí àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù bá wà ní (ìjókòó) ogún pípín, ẹ fún wọn nínú rẹ̀ (ṣíwájú kí ẹ tó pín ogún), kí ẹ sì sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn

[9] Àwọn (olùpíngún àti alágbàwò ọmọ òrukàn) tí ó bá jẹ́ pé àwọn náà máa fi ọmọ wẹ́wẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń páyà lórí wọn, kí wọ́n yáa bẹ̀rù Allāhu. Kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa (fún ọmọ òrukàn)

[10] Dájúdájú àwọn t’ó ń jẹ dúkìá ọmọ òrukàn pẹ̀lú àbòsí, Iná kúkú ni wọ́n ń jẹ sínú ikùn wọn. Wọ́n sì máa wọ inú Iná t’ó ń jò

[11] Allāhu ń pàṣẹ fun yín nípa (ogún tí ẹ máa pín fún) àwọn ọmọ yín; ti ọkùnrin ni irú ìpín ti obìnrin méjì. Tí wọ́n bá sì jẹ́ obìnrin (nìkan) méjì sókè, tiwọn ni ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ohun tí (òkú) fi sílẹ̀. Tí ó bá jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo, ìdajì ni tirẹ̀. Ti òbí rẹ̀ méjèèjì, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì nínú ohun tí òkú fi sílẹ̀, tí ó bá ní ọmọ láyé. Tí kò bá sì ní ọmọ láyé, tí ó sì jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì l’ó máa jogún rẹ̀, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ni ti ìyá rẹ̀. Tí ó bá ní arákùnrin (tàbí arábìnrin), ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìyá rẹ̀, (gbogbo rẹ̀) lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ó sọ tàbí gbèsè. Àwọn bàbá yín àti àwọn ọmọkùnrin yín; ẹ̀yin kò mọ èwo nínú wọn ló máa mú àǹfààní ba yín jùlọ. (Ìpín) ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[12] Tiyín ni ìlàjì ohun tí àwọn ìyàwó yín fi sílẹ̀, tí wọn kò bá ní ọmọ. Tí wọ́n bá sì ní ọmọ, tiyín ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí wọ́n fi sílẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè. Tiwọn sì ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí ẹ fi sílẹ̀, tí ẹ̀yin kò bá ní ọmọ láyé. Tí ẹ bá ní ọmọ láyé, ìdá kan nínú ìdá mẹ́jọ ni tiwọn nínú ohun tí ẹ fi sílẹ̀ lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ẹ sọ tàbí gbèsè. Tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ jogún rẹ̀ kò bá ní òbí àti ọmọ, tí ó sì ní arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì. Tí wọ́n bá sì pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ, wọn yóò dìjọ pín ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè, tí kò níí jẹ́ ìpalára. Òfin kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Aláfaradà

[13] Ìyẹn ni àwọn ẹnu-àlà (tí) Allāhu (gbékalẹ̀ fún ogún pípín). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá

[14] Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó sì ń tayọ àwọn ẹnu-àlà tí Allāhu gbékalẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú Iná kan. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì ń bẹ fún un

[15] Àwọn t’ó ń ṣe sìná nínú àwọn obìnrin yín, ẹ wá ẹlẹ́rìí mẹ́rin nínú yín tí ó máa jẹ́rìí lé wọn lórí. Tí wọ́n bá jẹ́rìí lé wọn lórí, kí ẹ dè wọ́n mọ́ inú ilé títí ikú yóò fi pa wọ́n tàbí (títí) Allāhu yóò fi fún wọn ní ọ̀nà (mìíràn)

[16] Àwọn méjì tí wọ́n ṣe (sìná) nínú yín, kí ẹ (fẹnu) bá wọn wí. Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣàtúnṣe, kí ẹ mójú kúrò lára wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[17] Ìronúpìwàdà tí Allāhu yóò gbà ni ti àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan. Lẹ́yìn náà, wọ́n ronú pìwàdà láìpẹ́. Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[18] Kò sí ìronúpìwàdà fún àwọn t’ó ń ṣe aburú títí ikú fi dé bá ọ̀kan nínú wọn, kí ó wá wí pé: “Dájúdájú èmi ronú pìwàdà nísinsìn yìí.” (Kò tún sí ìronúpìwàdà) fún àwọn t’ó kú sípò aláìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyẹn, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta eléro sílẹ̀ dè wọ́n

[19] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kò lẹ́tọ̀ọ́ fun yín láti jẹ àwọn obìnrin mógún pẹ̀lú ipá (bíi ṣíṣú obìnrin lópó.) Ẹ má sì dí wọn lọ́wọ́ láti kó apá kan n̄ǹkan tí ẹ fún wọn lọ àyàfi tí wọ́n bá hùwà ìbàjẹ́ pọ́nńbélé. Ẹ bá wọn lòpọ̀ pẹ̀lú dáadáa. Tí ẹ bá kórira wọn, ó lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí Allāhu sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore sínú rẹ̀

[20] Tí ẹ bá sì fẹ́ fi ìyàwó kan pààrọ̀ àyè ìyàwó kan, tí ẹ sì ti fún ọ̀kan nínú wọn ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá, ẹ ò gbọdọ̀ gba n̄ǹkan kan nínú rẹ̀ mọ́. Ṣé ẹ̀yin yóò gbà á ní ti àdápa irọ́ (tí ẹ̀ ń pa mọ́ wọn) àti ẹ̀ṣẹ̀ tó fojú hàn (tí ẹ̀ ń dá nípa wọn)

[21] Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè gbà á padà nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ ti wọlé tọ’ra yín, tí wọ́n sì ti gba àdéhùn t’ó nípọn lọ́wọ́ yín

[22] Ẹ má ṣe fẹ́ ẹni tí àwọn bàbá yín ti fẹ́ nínú àwọn obìnrin àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ àti ohun ìkórira. Ó sì burú ní ọ̀nà

[23] A ṣe é ní èèwọ̀ fun yín (láti fẹ́) àwọn ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin yín àti àwọn arábìnrin yín àti àwọn arábìnrin bàbá yín àti àwọn arábìnrin ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin yín àti àwọn ìyá yín tí ó fun yín ní ọyàn mu àti arábìnrin yín nípasẹ̀ ọyàn àti àwọn ìyá ìyàwó yín àti àwọn ọmọbìnrin ìyàwó yín tí ẹ gbà tọ́, èyí t’ó wà nínú ilé yín, tí ẹ sì ti wọlé tọ àwọn ìyá wọn, - tí ẹ̀yin kò bá sì tí ì wọlé tọ̀ wọ́n, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín (láti fẹ́ ọmọbìnrin wọn), - àti àwọn ìyàwó ọmọ yín, èyí tí ó ti ìbàdí yín jáde. (Ó tún jẹ́ èèwọ̀) láti fẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò papọ̀ àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn Àṣàkẹ́-ọ̀run

[24] (Ó tún jẹ́ èèwọ̀ láti fẹ́) àwọn abilékọ nínú àwọn obìnrin àyàfi àwọn ẹrúbìnrin yín. Òfin Allāhu nìyí lórí yín. Wọ́n sì ṣe ẹni t’ó ń bẹ lẹ́yìn àwọn wọ̀nyẹn ní ẹ̀tọ́ fun yín pé kí ẹ wá wọn fẹ́ pẹ̀lú dúkìá yín; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ ìyàwó, láì nìí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì síso). Ẹni tí ẹ bá sì fẹ́ ní fífẹ́ ìyàwó, tí ẹ sì ti jẹ ìgbádùn oorun ìfẹ́ lára wọn fún ìgbà díẹ̀ (àmọ́ tí ẹ fẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀), ẹ fún wọn ní sọ̀daàkí wọn. Ọ̀ran-anyàn ni. Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ jọ yọ́nú sí (láti fojú fò láààrin ara yín) lẹ́yìn sọ̀daàkí (t’ó jẹ́ ọ̀ran-anyàn). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[25] Ẹni tí kò bá lágbára ọrọ̀ nínú yín láti fẹ́ àwọn olómìnira onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, kí ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúbìnrin yín, onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ yín, ara kan náà (sì) ni yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda àwọn olówó wọn. Kí ẹ sì fún wọn ní sọ̀daàkí wọn ní ọ̀nà t’ó dára, (ìyẹn) àwọn ọmọlúàbí (ẹrúbìnrin), yàtọ̀ sí àwọn aṣẹ́wó àti ọ̀dọ́kọ. Nígbà tí wọ́n bá sì di abilékọ, tí wọ́n bá (tún) lọ ṣe sìná, ìlàjì ìyà tí ń bẹ fún àwọn olómìnira ni ìyà tí ń bẹ fún wọn. (Fífẹ́ ẹrúbìnrin), ìyẹn wà fún ẹni t’ó ń páyà ìnira (sìná) nínú yín. Àti pé kí ẹ ṣe sùúrù lóore jùlọ fun yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[26] Allāhu fẹ́ ṣàlàyé (òfin) fun yín, Ó fẹ́ tọ yín sí ọ̀nà àwọn t’ó ṣíwájú yín, Ó sì fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[27] Àti pé Allāhu fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Àwọn t’ó sì ń tẹ̀lé ìfẹ́-adùn ayé sì ń fẹ́ kí ẹ yẹ̀ kúrò (nínú ẹ̀sìn) ní yíyẹ̀ t’ó tóbi

[28] Allāhu fẹ́ ṣe ìrọ̀rùn fun yín; A sì ṣẹ̀dá ènìyàn ní ọ̀lẹ

[29] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín àyàfi kí ó jẹ́ òwò ṣíṣe pẹ̀lú ìyọ́nú láààrin ara yín. Ẹ má ṣe para yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú si yín

[30] Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe ìyẹn láti fi tayọ ẹnu-àlà àti láti fi ṣe àbòsí, láìpẹ́ A máa mú un wọ inú Iná. Ìrọ̀rùn sì ni ìyẹn jẹ́ fún Allāhu

[31] Tí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá tí A kọ̀ fun yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fun yín, A sì máa mu yín wọ àyè alápọ̀n-ọ́nlé

[32] Ẹ má ṣe jẹ̀rankàn ohun tí Allāhu fi ṣ’oore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan. Ìpín (ẹ̀san) ń bẹ fún àwọn ọkùnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, ìpín (ẹ̀san) sì ń bẹ fún àwọn obìnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Kí ẹ sì tọrọ lọ́dọ̀ Allāhu àlékún oore Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[33] Ìkọ̀ọ̀kan (àwọn dúkìá) ni A ti ṣe àdáyanrí rẹ̀ fún àwọn tí ó máa jogún rẹ̀ nínú ohun tí àwọn òbí àti ẹbí fi sílẹ̀. Àwọn tí ẹ sì búra fún (pé ẹ máa fún ní n̄ǹkan), ẹ fún wọn ní ìpín wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan

[34] Àwọn ọkùnrin ni òpómúléró (aláṣẹ) fún àwọn obìnrin nítorí pé Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn. Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n. Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan wá wọn níjà. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi

[35] Tí ẹ bà sì mọ̀ pé ìyapa wà láààrin àwọn méjèèjì, ẹ gbé olóye kan dìde láti inú ẹbí ọkọ àti olóye kan láti inú ẹbí ìyàwó. Tí àwọn (tọkọ tìyàwó) méjèèjì bá ń fẹ́ àtúnṣe, Allāhu yóò fi àwọn (olóye méjèèjì) ṣe kòńgẹ́ àtúnṣe lórí ọ̀rọ̀ ààrin wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alámọ̀tán

[36] Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I. Ẹ ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì àti ẹbí àti àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù àti aládùúgbò t’ó súnmọ́ àti aládùúgbò t’ó jìnnà àti ọ̀rẹ́ alábàárìn àti ẹni tí agara dá lórí ìrìn-àjò àti àwọn ẹrú yín. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ onígbèéraga, afọ́nnu

[37] Àwọn t’ó ń ṣahun, (àwọn) t’ó ń pa ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe àti (àwọn) t’ó ń fi ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ pamọ́; A ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[38] Àwọn t’ó ń ná owó wọn pẹ̀lú ṣekárími, tí wọn kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ẹnikẹ́ni tí Èṣù bá jẹ́ ọ̀rẹ́ fún, ó burú ní ọ̀rẹ́

[39] Kí ni ìpalára tí ó máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, tí wọ́n sì ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún wọn? Allāhu sì jẹ́ Onímọ̀ nípa wọ́n

[40] Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí òdíwọ̀n ọmọ iná-igún. Tí ó bá jẹ iṣẹ́ rere, Ó máa ṣàdìpèlé (ẹ̀san) rẹ̀. Ó sì máa fún (olùṣe rere) ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[41] Báwo ni ọ̀rọ̀ wọn yóò ti rí nígbà tí A bá mú ẹlẹ́rìí jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, tí A sì mú ìwọ jáde ní ẹlẹ́rìí lórí àwọn wọ̀nyí

[42] Ní ọjọ́ yẹn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì yapa Òjíṣẹ́, wọ́n á fẹ́ kí àwọn bá ilẹ̀ dọ́gba (kí wọ́n di erùpẹ̀). Wọn kò sì lè fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́ fún Allāhu

[43] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe súnmọ́ ìrun kíkí nígbà tí ọtí bá ń pa yín títí ẹ máa fi mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ àti àwọn oníjánnábà, àfi àwọn olùkọjá nínú mọ́sálásí, títí ẹ máa fi wẹ̀ (ìwẹ̀ jánnábà). Tí ẹ bá sì jẹ́ aláìsàn tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ọ̀kan nínú yín dé láti ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ẹ súnmọ́ obínrin (yín), tí ẹ kò rí omi, ẹ fi erùpẹ̀ t’ó dára ṣe táyàmọ́mù; ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòójúkúrò, Aláforíjìn

[44] Ṣé o ò rí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń ra ìṣìnà, tí wọ́n sì fẹ́ kí ẹ ṣìnà

[45] Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn ọ̀tá yín. Allāhu tó ní Aláàbò. Allāhu sì tó ní Alárànṣe

[46] Ó ń bẹ nínú àwọn yẹhudi, àwọn t’ó ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbọ́, a sì yapa. Gbọ́, a ò gba tìrẹ. Òmùgọ̀ wa.” Wọ́n ń fi ahọ́n wọn yí ọ̀rọ̀ sódì àti pé wọ́n ń bu ẹnu-àtẹ́ lu ẹ̀sìn. tí ó bá jẹ́ pé wọ́n sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e. Gbọ́, kí o sì kíyè sí wa”, ìbá dára fún wọn, ìbá sì tọ̀nà jùlọ. Ṣùgbọ́n Allāhu fi wọ́n gégùn-ún nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn)

[47] Ẹ̀yin tí A fún ní tírà, ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín, ṣíwájú kí Á tó fọ́ àwọn ojú kan, A sì máa dá a padà sí (ìpàkọ́) lẹ́yìn wọn, tàbí kí Á ṣẹ́bi lé wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ́bi lé ìjọ Sabt. Àti pé àṣẹ Allāhu máa ṣẹ

[48] Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá

[49] Ṣé o ò rí àwọn t’ó ń ṣàfọ̀mọ́ ara wọn ni? Kò sì rí bẹ́ẹ̀, Allāhu l’Ó ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Kò sì níí ṣàbòsí bín-íntín sí wọn

[50] Wo bí wọ́n ṣe ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Ó sì tó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé

[51] Ṣé o ò rí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń gbàgbọ́ nínú idán àti òrìṣà, wọ́n sì ń wí fún àwọn aláìgbàgbọ́ pé: “Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) wọ̀nyí mọ̀nà ju àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo.”

[52] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣẹ́bi lé. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá sì ṣẹ́bi lé, o ò níí rí alárànṣe kan fún un

[53] Tàbí ìpín kan ń bẹ fún wọn nínú ìjọba (Wa) ni? Ti ó bá rí bẹ́ẹ̀ wọn kò níí fún àwọn ẹ̀nìyàn ní èékán kóró dàbínú

[54] Tàbí wọ́n ń ṣe ìlara àwọn ènìyàn lórí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ ni? Dájúdájú A fún àwọn ẹbí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (sunnah). A sì fún wọn ní ìjọba t’ó tóbi

[55] Nítorí náà, ó ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀. Jahanamọ sì tó ní iná t’ó ń jò

[56] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, láìpẹ́ A máa mú wọn wọ inú Iná. Ìgbàkígbà tí awọ ara wọn bá jóná, A óò máa pààrọ̀ awọ ara mìíràn fún wọn kí wọ́n lè máa tọ́ ìyà wò lọ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[57] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, A óò mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Àwọn ìyàwó mímọ́ ń bẹ fún wọn nínú rẹ̀. A sì máa fi wọ́n sí abẹ́ ibòji t’ó máa ṣíji bò wọ́n dáradára

[58] Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ dá àgbàfipamọ́ padà fún àwọn olówó wọn. Àti pé nígbà tí ẹ bá ń dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, ẹ dájọ́ pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu ń fi n̄ǹkan t’ó dára ṣe wáàsí fun yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran

[59] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà àti àwọn aláṣẹ nínú yín. Nítorí náà, tí ẹ bá yapa ẹnu sí kiní kan, ẹ ṣẹ́rí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ fún ìkángun ọ̀rọ̀

[60] Ṣé o ò rí àwọn t’ó ń sọ̀rọ̀ (tí kò sì rí bẹ́ẹ̀) pé dájúdájú àwọn gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, tí wọ́n sì ń gbèrò láti gbé ẹjọ́ lọ bá òrìṣà, A sì ti pa wọ́n láṣẹ pé kí wọ́n lòdì sí i. Èṣù sì fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà ní ìṣìnà t’ó jìnnà

[61] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ẹ wá bá Òjíṣẹ́.”, o máa rí àwọn mùnááfìkí tí wọn yóò máa ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ rẹ tààrà

[62] Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọ́n tì síwájú, lẹ́yìn náà wọ́n máa wá bá ọ, wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé kò sí ohun tí a gbà lérò bí kò ṣe dáadáa àti ìrẹ́pọ̀

[63] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣe wáàsí fún wọn, kí o sì bá wọn sọ ọ̀rọ̀ t’ó lágbára nípa ara wọn

[64] A ò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi nítorí kí wọ́n lè tẹ̀lé e pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n wá bá ọ, wọ́n sì tọrọ àforíjìn Allāhu, tí Òjíṣẹ́ sì tún bá wọn tọrọ àforíjìn, wọn ìbá kúkú rí Allāhu ní Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[65] Rárá, Èmi fi Olúwa rẹ búra pé wọn kò tí ì gbàgbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi gbà ọ́ ní olùdájọ́ lórí ohun tí ó bá dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Lẹ́yìn náà, wọn kò níí ní ẹ̀hónú kan sí ìdájọ́ tí o bá dá. Wọ́n sì máa gbà pátápátá

[66] Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún wọn pé: "Ẹ para yín tàbí ẹ jáde kúrò nínú ìlú yín," wọn kò níí ṣe é àfi díẹ̀ nínú wọn. Tí ó bá tún jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun tí A fi ń ṣe wáàsí fún wọn ni, ìbá jẹ́ oore àti ìdúróṣinṣin tó lágbára jùlọ fún wọn

[67] Nígbà náà, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Wa

[68] Àti pé dájúdájú Àwa ìbá tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà

[69] Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, àwọn olódodo, àwọn t’ó kú s’ójú ogun ẹ̀sìn àti àwọn ẹni rere. Àwọn wọ̀nyẹn sì dára ní alábàárìn

[70] Oore àjùlọ yẹn máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu; Allāhu sì tó ní Onímọ̀

[71] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú ohun ìṣọ́ra yín lọ́wọ́, kí ẹ sì tú jáde s’ójú ogun ẹ̀sìn níkọ̀níkọ̀ tàbí kí ẹ tú jáde ní àpapọ̀

[72] Dájúdájú ó ń bẹ nínú yín ẹni t’ó ń fà sẹ́yìn. Tí àdánwó kan bá kàn yín, ó máa wí pé: "Allāhu kúkú ti ṣe ìdẹ̀ra fún mi nítorí pé èmi kò sí níbẹ̀ pẹ̀lú wọn

[73] Dájúdájú tí oore àjùlọ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá sì tẹ̀ yín lọ́wọ́, dájúdájú ó máa sọ̀rọ̀ - bí ẹni pé kò sí ìfẹ́ láààrin ẹ̀yin àti òun (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) - pé: “Yéè! Èmi ìbá wà pẹ̀lú wọn, èmi ìbá jẹ èrè ńlá.”

[74] Nítorí náà, kí àwọn t’ó ń fi ayé ra ọ̀run máa jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jagun nítorí ẹ̀sìn Allāhu, yálà wọ́n pa á tàbí ó ṣẹ́gun, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá

[75] Kí l’ó ṣe yín tí ẹ ò níí jagun fún ẹ̀sìn Allāhu, nígbà tí àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé (sì ń bẹ lórí ilẹ̀), àwọn t’ó ń sọ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú ìlú yìí, ìlú àwọn alábòsí. Fún wa ní aláàbò kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ́. Kí Ó sì fún wa ní alárànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ.”

[76] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ń jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń jagun fún ẹ̀sìn òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ja àwọn ọ̀rẹ́ Èṣù lógun. Dájúdájú ète Èṣù, ó jẹ́ ohun tí ó lẹ

[77] Ṣé ó ò rí àwọn tí A sọ fún pé: “Ẹ dá’wọ́ ogun ẹ̀sìn dúró, ẹ máa kírun (lọ ná), kí ẹ sì máa yọ Zakāh.” Ṣùgbọ́n nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn jíjà ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí, ìgbà náà ni apá kan nínú wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn bí ẹni tí ń bẹ̀rù Allāhu tàbí tí ìbẹ̀rù rẹ̀ le koko jùlọ. Wọ́n sì wí pé: "Olúwa wa, nítorí kí ni O fi ṣe ogun ẹ̀sìn jíjà ní ọ̀ran-anyàn lé wa lórí? Kúkú lọ́ wa lára di ìgbà díẹ̀ sí i." Sọ pé: “Bín-íntín ní ìgbádùn ayé, ọ̀run lóore jùlọ fún ẹni t’ó bá bẹ̀rù Allāhu. A ò sì níí ṣàbòsí bín-íntín si yín.”

[78] Ibikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí l’ó ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan

[79] Ohunkóhun t’ó bá tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nínú oore, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú aburú, láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ni. A rán ọ níṣẹ́ pé kí o jẹ́ Òjíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí

[80] Ẹnikẹ́ni t’ó bá tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, ó ti tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì pẹ̀yìndà, A ò rán ọ níṣẹ́ olùṣọ́ lórí wọn

[81] Wọ́n ń wí pé: “A tẹ̀lé àṣẹ rẹ.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ, igun kan nínú wọn máa gbìmọ̀ n̄ǹkan tí ó yàtọ̀ sí èyí tí ń sọ (lọ́sàn-án). Allāhu sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ń gbìmọ̀ lóru. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó Aláàbò

[82] Ṣé wọn kò ronú nípa al-Ƙur’ān ni? Tí ó bá jẹ́ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn yàtọ̀ sí Allāhu, wọn ìbá rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìtakora nínú rẹ̀

[83] Nígbà tí ọ̀rọ̀ ìfàyàbalẹ̀ tàbí ìpáyà kan bá dé bá wọn, wọ́n sì máa tàn án kálẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́rí rẹ̀ sí (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ àti àwọn aláṣẹ (ìyẹn, àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn) nínú wọn, àwọn t’ó ń yọ òdodo jáde nínú ọ̀rọ̀ nínú wọn ìbá mọ̀ ọ́n. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín ni, ẹ̀yin ìbá tẹ̀lé Èṣù àfi ìba díẹ̀ (nínú yín)

[84] Nítorí náà, jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò là á bọ ẹnì kan lọ́rùn àfi ìwọ. Kí o sì gbẹ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóǹgbẹ ogun ẹ̀sìn jíjà. Ó ṣeé ṣe kí Allāhu ká ọwọ́jà àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ dúró. Àti pé Allāhu le jùlọ (níbi) ìjà. Ó sì le jùlọ níbi ìjẹni-níyà

[85] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ rere, ó máa rí ìpín ẹ̀san nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ aburú, ó máa rí ìpín ẹ̀ṣẹ̀ nínú rẹ̀. Allāhu sì jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan

[86] Nígbà tí wọ́n bá ki yín ní kíkí kan, ẹ kí wọn (padà) pẹ̀lú èyí t’ó dára jù ú lọ tàbí kí ẹ dá a padà (pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ki yín). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣírò lórí gbogbo n̄ǹkan

[87] Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ta sì ni ó sọ òdodo ju Allāhu lọ

[88] Kí ni ó máa mu yín pín sí ìjọ méjì nípa àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí! Allāhu l’Ó dá wọn padà sẹ́yìn nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ fi ẹni tí Allāhu ṣì lọ́nà mọ̀nà ni? Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò níí rí ọ̀nà kan fún un

[89] Wọ́n fẹ́ kí ẹ ṣàì gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́, kí ẹ lè jọ di ẹgbẹ́ kan náà. Nítorí náà, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò nínú wọn títí wọ́n fi máa ṣí kúrò nínú ìlú ẹbọ wá sí ìlú ’Islām fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Tí wọ́n bá kẹ̀yìn (sí ṣíṣe hijrah náà), ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ẹ bá ti rí wọn. Kí ẹ sì má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò àti olùrànlọ́wọ́ kan nínú wọn

[90] Àyàfi àwọn t’ó bá dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Tàbí wọ́n wá ba yín, tí ọkàn wọn ti pami láti ba yín jà tàbí láti bá àwọn ènìyàn wọn jà. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá fún wọn lágbára (akin-ọkàn) lórí yín, wọn ìbá sì jà yín lógun. Nítorí náà, tí wọ́n bá yẹra fun yín, tí wọn kò sì jà yín lógun, tí wọ́n sì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fun yín, nígbà náà Allāhu kò fun yín ní ọ̀nà lórí wọn (láti jà wọ́n lógun)

[91] Ẹ máa rí àwọn ẹlòmíìràn tí wọ́n fẹ́ fi yín lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì fẹ́ fi àwọn ènìyàn wọn lọ́kàn balẹ̀ (pé) nígbàkígbà tí wọ́n bá dá wọn padà sínú ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) ni wọ́n ń padà sínú rẹ̀. Tí wọn kò bá yẹra fun yín, tí wọn kò juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fun yín, tí wọn kò sì dáwọ́ jíjà yín lógun dúró, nígbà náà ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu sì fun yín ní agbára t’ó yanjú lórí wọn (láti jà wọ́n lógun)

[92] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo kan láti pa onígbàgbọ́ òdodo kan àyàfi tí ó bá ṣèèsì. Ẹni tí ó bá sì ṣèèsì pa onígbàgbọ́ òdodo kan, ó máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ó sì máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn òkú àfi tí wọ́n bá fi tọrẹ (fún un). Tí ó bá sì wà nínú àwọn ènìyàn kan tí ó jẹ́ ọ̀tá fun yín, onígbàgbọ́ òdodo sì ni (ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Tí ó bá jẹ́ ìjọ tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn, ó máa san owó ẹ̀mí fún wọn. Ó sì máa tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí ẹrú onígbàgbọ́ òdodo, ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. (Ọ̀nà) ìronúpìwàdà kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (nìyí). Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[93] Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa onígbàgbọ́ òdodo kan, iná Jahanamọ ni ẹ̀san rẹ̀. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Allāhu yóò bínú sí i. Ó máa fi ṣẹ́bi lé e. Ó sì ti pèsè ìyà t’ó tóbi sílẹ̀ dè é

[94] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò ogun ẹ̀sìn Allāhu, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn). Ẹ sì má ṣe sọ fún ẹni tí ó bá sálámọ̀ si yín pé kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo nítorí pé ẹ̀yin ń wá dúkìá ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu kúkú ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ ogun wà. Báyẹn ni ẹ̀yin náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, Allāhu sì ṣe ìdẹ̀ra (ẹ̀sìn) fun yín. Nítorí náà, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn náà). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[95] Àwọn olùjókòó sínú ilé nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, yàtọ̀ sí àwọn aláìlera, àti àwọn olùjagun fún ẹ̀sìn Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn, wọn kò dọ́gba. Allāhu fi ipò kan ṣoore àjùlọ fún àwọn olùjagun fún ẹ̀sìn Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé. Olúkùlùkù (wọn) ni Allāhu ṣe àdéhùn ohun rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) fún. Allāhu gbọ́lá fún àwọn olùjagun ẹ̀sìn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé pẹ̀lú ẹ̀san ńlá

[96] àwọn ipò kan, àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn Àṣàkẹ́-ọ̀run

[97] Dájúdájú àwọn tí mọlāika gba ẹ̀mí wọn, (lásìkò) tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, (àwọn mọlāika) sọ pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe (nínú ẹ̀sìn)?” Wọ́n wí pé: “Wọ́n dá wa lágara lórí ilẹ̀ ni.” (Àwọn mọlāika) sọ pé: “Ṣé ilẹ̀ Allāhu kò fẹ̀ tó (fun yín) láti gbé ẹ̀sìn yín sá lórí ilẹ̀?” Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ó sì burú ní ìkángun

[98] Àyàfi àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí kò ní ìkápá ọgbọ́n kan, tí wọn kò sì dá ọ̀nà mọ̀ (dé ìlú Mọdīnah)

[99] Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn, ó súnmọ́ kí Allāhu ṣàmójúkúrò fún wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn

[100] Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ìlú rẹ̀ jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, ó máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ibùsásí àti ìgbàláàyè lórí ilẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde kúrò nínú ilé rẹ̀ (tí ó jẹ́) olùfìlú-sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ikú bá a (lójú ọ̀nà), ẹ̀san rẹ̀ kúkú ti wà lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[101] Nígbà tí ẹ bá ṣe ìrìn-àjò lórí ilẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín láti dín ìrun kù, tí ẹ̀yin bá ń bẹ̀rù pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò fòòró yín. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, wọ́n jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín

[102] Nígbà tí o bá wà láààrin wọn, gbé ìrun dúró fún wọn. Kí igun kan nínú wọn kírun pẹ̀lú rẹ, kí wọ́n mú n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n bá sì forí kanlẹ̀ (tí wọ́n parí ìrun), kí wọn bọ́ sẹ́yìn yín, kí igun mìíràn tí kò tí ì kírun wá kírun pẹ̀lú rẹ. Kí wọ́n mú ìṣọ́ra wọn àti n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ kí ẹ gbàgbé àwọn n̄ǹkan ìjagun yín àti n̄ǹkan ìgbádùn yín, kí wọ́n lè kọlù yín ní ẹ̀ẹ̀ kan náà. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín tí ó bá jẹ́ pé ìpalára kan ń bẹ fun yín látara òjò tàbí (pé) ẹ jẹ́ aláìsàn, pé kí ẹ fi n̄ǹkan ìjagun yín sílẹ̀ (lórí ìrun). Ẹ mú n̄ǹkan ìṣọ́ra yín lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[103] Nígbà tí ẹ bá parí ìrun, kí ẹ ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní ìdúró, ìjókòó àti ìdùbúlẹ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá sì fọkàn balẹ̀ (ìyẹn nígbà tí ẹ bá wọnú ìlú), kí ẹ kírun (ní pípé). Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[104] Ẹ má ṣe káàárẹ̀ nípa wíwá àwọn ènìyàn náà (láti jà wọ́n lógun). Tí ẹ̀yin bá ń jẹ ìrora (ọgbẹ́), dájúdájú àwọn náà ń jẹ ìrora (ọgbẹ́) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe ń jẹ ìrora. Ẹ̀yin sì ń retí ohun tí àwọn kò retí lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[105] Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí kí o lè baà ṣèdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn pẹ̀lú ohun tí Allāhu fi hàn ọ́. Má ṣe jẹ́ olùgbèjà fún àwọn oníjàǹbá

[106] Tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[107] Má ṣe bá àwọn t’ó ń jàǹbá ẹ̀mí ara wọn wá àwíjàre. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ oníjàǹbá, ẹlẹ́ṣẹ̀

[108] Wọ́n ń fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn, wọn kò sì lè fara pamọ́ fún Allāhu (nítorí pé) Ó wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀) nígbà tí wọ́n ń gbìmọ̀ ohun tí (Allāhu) kò yọ́nú sí nínú ọ̀rọ̀ sísọ. Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[109] Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí ni ẹ̀ ń bá wọn mú àwíjàre wá nílé ayé. Ta ni ó máa bá wọn mú àwíjàre wá ní ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde? Tàbí ta ni ó máa jẹ́ aláàbò fún wọn

[110] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan tàbí tí ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, ó máa bá Allāhu ní Aláforíjìn, Aláàánú

[111] Ẹnikẹ́ni tí ó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, ó dá a fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[112] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣìṣe kan tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, ó dì í ru aláìmọwọ́-mẹsẹ̀, ó ti dá ọ̀ràn ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé

[113] Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ tí ń bẹ lórí rẹ ni, igun kan nínú wọn ìbá ti fẹ́ ṣì ọ́ lọ́nà. Wọn kò sì níí ṣi ẹnì kan lọ́nà àfi ara wọn. Wọn kò sì lè fi n̄ǹkan kan kó ìnira bá ọ. Allāhu sì sọ Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah) kalẹ̀ fún ọ. Ó tún fi ohun tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ mọ̀ ọ́; oore àjùlọ Allāhu lórí rẹ jẹ́ ohun t’ó tóbi

[114] Kò sí oore nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn àfi ẹni tí ó bá pàṣẹ ọrẹ títa tàbí iṣẹ́ rere tàbí àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn láti fi wá ìyọ́nú Allāhu, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san t’ó tóbi

[115] Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí Òjíṣẹ́ náà lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú han sí i kedere, tí ó tún tẹ̀lé ọ̀nà t’ó yàtọ̀ sí ti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, A óò dojú rẹ̀ kọ ohun tí ó dojú ara rẹ̀ kọ (nínú ìṣìnà), A ó sì mú un wọ inú iná Jahanamọ. Ó sì burú ní ìkángun

[116] Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà

[117] Wọn kò pe kiní kan lẹ́yìn Allāhu bí kò ṣe àwọn abo òrìṣà. Wọn kò sì pe kiní kan bí kò ṣe Èṣù olùyapa

[118] Allāhu ṣẹ́bi lé Èṣù. Ó sì wí pé: "Dájúdájú mo máa mú ìpín tí wọ́n pín fún mi nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ

[119] Dájúdájú mo máa ṣì wọ́n lọ́nà. Mo máa fi èròkerò sínú ọkàn wọn. Mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa gé etí ẹran-ọ̀sìn (láti yà á sọ́tọ̀ fún òrìṣà). Mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa yí ẹ̀dá Allāhu padà." Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú Èṣù ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu, dájúdájú ó ti ṣòfò ní òfò pọ́nńbélé

[120] Èṣù ń ṣàdéhùn fún wọn, ó sì ń fi ìfẹ́-irọ́ sínú ọkàn wọn. Èṣù kò sì ṣàdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn

[121] Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; wọn kò sì níí rí ibùsásí kan

[122] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, A máa mú wọn wọ inu àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀ títí láéláé. (Ó jẹ́) àdéhùn tí Allāhu ṣe ní ti òdodo. Ta sì ni ó sọ òdodo ju Allāhu lọ

[123] Kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn yín, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn àwọn ahlu-l-kitāb (ni òṣùwọ̀n ìdájọ́ ọ̀run. Àmọ́,) ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan, A óò san án ní ẹ̀san rẹ̀; kò sì níí rí aláfẹ̀yìntì tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu

[124] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ rere, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, onígbàgbọ́ òdodo sì ni, àwọn wọ̀nyẹn l’ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí èékán kóró dàbínù fún wọn

[125] Ta l’ó dára ní ẹ̀sìn ju ẹni tí ó jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, olùṣe-rere sì tún ni, ó tún tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām? Allāhu sì mú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní àyànfẹ́

[126] Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa gbogbo n̄ǹkan

[127] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìdájọ́ nípa àwọn obìnrin. Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń sọ ìdájọ́ wọn fun yín. Ohun tí wọ́n ń ké fun yín nínú Tírà (al-Ƙur’ān náà ń sọ ìdájọ́ fun yín) nípa àwọn ọmọ-òrukàn lóbìnrin tí ẹ kì í fún ní ohun tí wọ́n kọ fún wọn (nínú ogún), tí ẹ tún ń ṣojú-kòkòrò láti fẹ́ wọn àti nípa àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọmọdé (tí ẹ̀ ń jẹ ogún wọn mọ́lẹ̀.) àti nípa pé kí ẹ dúró ti àwọn ọmọ òrukàn pẹ̀lú déédé. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ṣe ní rere, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀

[128] Tí obìnrin kan bá páyà ìṣe oríkunkun tàbí ìkẹ̀yìnsí láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì pé kí wọ́n ṣe àtúnṣe láààrin ara wọn. Àtúnṣe sì dára jú lọ. Wọ́n sì ti fi ahun àti ọ̀kánjúà ṣíṣe sínú ẹ̀mí ènìyàn. Tí ẹ bá ṣe rere, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[129] Ẹ ò lè ṣe déédé (nínú ìfẹ́) láààrin àwọn obìnrin, ẹ ò báà jẹ̀rankàn rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fì síbì kan tán ráúráú, kí ẹ má lọ pa (ẹnì kan) tì bí ohun àgbékọ́. Tí ẹ bá ṣàtúnṣe, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[130] Tí àwọn méjèèjì bá sì pínyà, Allāhu yóò rọ ìkíní kejì lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀ t’ó gbòòrò. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbòòrò (nínú ọrọ̀), Ọlọ́gbọ́n

[131] Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú A ti pa á láṣẹ fún àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti ẹ̀yin náa pé kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn (tí ẹyìn tọ́ sí)

[132] Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́

[133] Tí (Allāhu) bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò lórí ilẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn. Ó sì máa mú àwọn mìíràn wá. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí ìyẹn

[134] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san nílé ayé, ṣebí lọ́dọ̀ Allāhu ní ẹ̀san ayé àti ọ̀run wà. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran

[135] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí òdodo nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí nítorí ti Allāhu, kódà kí (ẹ̀rí jíjẹ́ náà) tako ẹ̀yin fúnra yín tàbí àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí; yálà ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí aláìní. Allāhu súnmọ́ (yín) ju àwọn méjèèjì lọ. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú láti má ṣe déédé. Tí ẹ bá yí ojú-ọ̀rọ̀ sódì tàbí tí ẹ bá gbúnrí kúrò (níbi déédé), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[136] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà tefétefé

[137] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n sì lékún sí i nínú àìgbàgbọ́, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fí ọ̀nà mọ̀ wọ́n

[138] Fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìró pé dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn

[139] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ṣé ẹ̀ ń wá agbára lọ́dọ̀ wọn ni? Dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo agbára pátápátá

[140] (Allāhu) kúkú ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fun yín nínú Tírà pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn āyah Allāhu pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe ẹ̀fẹ̀, ẹ má ṣe jókòó tì wọ́n nígbà náà títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ dájúdájú ẹ̀yin yóò dà bí irú wọn. Dájúdájú Allāhu yóò pa àwọn ṣòbẹ-ṣèlu mùsùlùmí pọ̀ mọ́ gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ nínú iná Jahanamọ

[141] (Àwọn ni) àwọn t’ó fẹ́ yọ̀ yín; tí ìṣẹ́gun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá jẹ́ tiyín, wọ́n á wí pé: “Ṣé àwa kò wà pẹ̀lú yín bí?” Tí ìpín kan bá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́, (àwọn mùnááfìkí) á wí pé: “Ṣé àwa kò ti ní ìkápá láti jẹ gàba le yín lórí (àmọ́ tí àwa kò ṣe bẹ́ẹ̀), ṣé àwa kò sì dáàbò bò yín tó lọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (títí ọwọ́ yín fi ba ọrọ̀-ogun, nítorí náà kí ni ìpín tiwa tí ẹ fẹ́ fún wa?)” Nítorí náà, Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde. Allāhu kò sì níí fún àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀nà (ìṣẹ́gun) kan lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[142] Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń tan Allāhu, Òun náà sì máa tàn wọ́n. Nígbà tí wọ́n bá dúró láti kírun, wọ́n á dúró (ní ìdúró) òròjú, wọn yó sì máa ṣe ṣekárími (lórí ìrun). Wọn kò sì níí ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu (lórí ìrun) àfi díẹ̀

[143] Wọ́n ń ṣe bàlàbàlà síhìn-ín sọ́hùn-ún, wọn kò jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí, wọn kò sì jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí ọ̀nà kan fún un

[144] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ yín). Ṣé ẹ fẹ́ ṣe n̄ǹkan tí Allāhu yóò fi ní ẹ̀rí pọ́nńbélé lọ́wọ́ láti jẹ yín níyà ni

[145] Dájúdájú àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí yóò wà nínú àjà ìsàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. O ò sì níí rí alárànṣe kan fún wọn

[146] Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n dúró ṣinṣin ti Allāhu, tí wọ́n sì ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn wọn fún Allāhu. Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Láìpẹ́ Allāhu máa fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ẹ̀san ńlá

[147] Kí ni Allāhu máa fi ìyà yín ṣe, tí ẹ bá dúpẹ́, tí ẹ sì gbàgbọ́ ní òdodo? Allāhu sì ń jẹ́ Olùmoore, Onímọ̀

[148] Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ sí ariwo èpè ṣíṣẹ́ (láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni) àyàfi ẹni tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Onímọ̀

[149] Tí ẹ bá ṣàfi hàn rere tàbí ẹ fi pamọ́ tàbí ẹ ṣàmójú kúrò níbi aburú, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Alágbára

[150] Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n fẹ́ ṣòpínyà láààrin Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú apá kan, a sì ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan,” wọ́n sì fẹ́ mú ọ̀nà kan tọ̀ (lẹ́sìn) láààrin ìyẹn

[151] Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́. A sì ti pèsè Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[152] Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọn kò sì ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn, láìpẹ́ àwọn wọ̀nyẹn, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[153] Àwọn ahlul-kitāb ń bi ọ́ léèrè pé kí o sọ tírà kan kalẹ̀ láti inú sánmọ̀. Wọ́n kúkú bi (Ànábì) Mūsā ní ohun tí ó tóbi ju ìyẹn lọ. Wọ́n wí pé: “Fi Allāhu hàn wá ní gban̄gba.” Nítorí náà, ohùn igbe láti inú sánmọ̀ gbá wọn mú nípasẹ̀ àbòsí ọwọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di n̄ǹkan tí wọ́n jọ́sìn fún lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé bá wọn. A tún ṣàmójú kúrò níbi ìyẹn. A sì fún (Ànábì) Mūsā ní ẹ̀rí pọ́nńbélé

[154] A gbé àpáta sókè orí wọn nítorí májẹ̀mu wọn. A sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùtẹríba.” A tún sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà ní ọjọ́ Sabt.” A sì gba àdéhùn t’ó nípọn lọ́wọ́ wọn

[155] Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn, ṣíṣàìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu, pípa tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́ àti wíwí tí wọ́n ń wí pé: “Ọkàn wa ti di.” – rárá, Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn ni nítorí àìgbàgbọ́ wọn. – Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn)

[156] Àti nítorí àìgbàgbọ́ wọn àti ọ̀rọ̀ wọn lórí Mọryam ní ti ìbànilórúkọjẹ́ t’ó tóbi (Allāhu tún fi èdídí dí ọkàn wọn)

[157] Àti nítorí ọ̀rọ̀ wọn (yìí): “Dájúdájú àwa pa Mọsīh, ‘Īsā ọmọ Mọryam, Òjíṣẹ́ Allāhu.” Wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni. Dájúdájú àwọn t’ó yapa-ẹnu nípa rẹ̀, kúkú wà nínú iyèméjì nínú rẹ̀; kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀ àfi títẹ̀lé èròkérò. Wọn kò pa á ní àmọ̀dájú. sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:7 sūrah al-’Ani‘ām; 6: 99 àti

[158] Rárá o, Allāhu gbé e wá sókè lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[159] Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn ahlul-kitāb (láyé nígbà tí ‘Īsā bá sọ̀kalẹ̀ padà láti ojú sánmọ̀) àfi kí ó gbà á gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú rẹ̀. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, ó sì máa jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn. àgbéga ipò gẹ́gẹ́ bí èyí t’ó jẹyọ nínú sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:176 àti sūrah Mọryam; 19:57) tàbí kí ó túmọ̀ sí àgbéga tara (ìyẹn gbígbé ara kúrò láti àyè ìsàlẹ̀ sí àyè òkè gẹ́gẹ́ bí èyí t’ó jẹyọ nínú sūrah Fātir; 35:10). Àmọ́ kò ní tàbí-ṣùgbọ́n nínú mọ́ pé nígbàkígbà tí harafi “إلى” bá ti tẹ̀lé “رفع” òkè sánmọ̀ keje ni Allahu wà nítorí pé inú sánmọ̀ yìí náà ni Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gùn lọ láti lọ gba ìrun wákàtí márùn-ún wá lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lásìkò ìrìn òru àti ìgun-sánmọ̀ gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi rinlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ sūrah al-’Isrọ̄’. Kódà tòhun ti bí àìgbàgbọ́ Fir‘aon ṣe gbópọn tó ó kúkú gbà pé sánmọ̀ ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) wà. Ó sì bẹ Hāmọ̄n ní ilé gíga fíofío kọ́. Ó fẹ́ yọjú wo Allāhu! (sūrah al-Ƙọsọs; 28:38). Nítorí náà

[160] Nítorí àbòsí láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n di yẹhudi, A ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa kan ní èèwọ̀ fún wọn, èyí tí wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn (tẹ́lẹ̀. A ṣe é ní èèwọ̀ fún wọn sẹ́) nípa bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu

[161] Àti gbígbà tí wọ́n ń gba owó èlé, tí A sì ti kọ̀ ọ́ fún wọn, àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ dúkìá àwọn ènìyàn lọ́nà èrú. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[162] Ṣùgbọ́n àwọn àgbà nínú ìmọ̀ nínú wọn àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, wọ́n gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, (wọ́n tún gbàgbọ́ nínú àwọn mọlāika) t’ó ń kírun. (Àwọn wọ̀nyẹn) àtí àwọn t’ó ń yọ Zakāh àti àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní ẹ̀san ńlá

[163] Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀), àti (Ànábì) ‘Īsā, ’Ayyūb, Yūnus, Hārūn àti Sulaemọ̄n. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr

[164] Àti àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A ti sọ ìtàn wọn fún ọ ṣíwájú pẹ̀lú àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ. Allāhu sì bá (Ànábì) Mūsā sọ̀rọ̀ tààrà

[165] (A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[166] Ṣùgbọ́n Allāhu ń jẹ́rìí sí ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àwọn mọlāika náà ń jẹ́rìí (sí i). Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí

[167] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n kúkú ti ṣìnà ní ìṣìnà t’ó jìnnà

[168] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣàbòsí, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fi ojú-ọ̀nà mọ̀ wọ́n

[169] Àyàfi ojú-ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu

[170] Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Òjíṣẹ́ náà ti dé ba yín pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kí ẹ gbà á gbọ́ l’ó dára jùlọ fun yín. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[171] Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fun yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo (tí ìjọ́sìn tọ́ sí). Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó

[172] Mọsīh kò kọ̀ láti jẹ́ ẹrú fún Allāhu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn mọlāika tí wọ́n súnmọ́ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti jọ́sìn fún Un, tí ó tún ṣègbéraga, (Allāhu) yóò kó wọn jọ papọ̀ pátápátá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[173] Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn. Ó sì máa ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Ní ti àwọn t’ó bá sì kọ̀ (láti jọ́sìn fún Allāhu), tí wọ́n sì ṣègbéraga, (Allāhu) yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro. Wọn kò sì níí rí alátìlẹ́yìn tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu

[174] Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. A sì tún sọ ìmọ́lẹ̀ t’ó yanjú kalẹ̀ fun yín

[175] Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, tí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì Í, Ó máa fi wọ́n sínú ìkẹ́ àti ọlá kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó sì máa fi wọ́n mọ ọ̀nà tààrà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[176] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìbéèrè, sọ pé: “Allāhu ń fun yín ní ìdájọ́ nípa ẹni tí kò ní òbí, kò sì ní ọmọ. Tí ènìyàn kan bá kú, tí kò ní ọmọ láyé, tí ó sì ní arábìnrin kan, ìdajì ni tirẹ̀ nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. (Arákùnrin) l’ó máa jẹ gbogbo ogún arábìnrin rẹ̀, tí kò bá ní ọmọ láyé. Tí arábìnrin bá sì jẹ́ méjì, ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ni tiwọn nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì jẹ́ arákùnrin (púpọ̀) lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ti ọkùnrin kan ni ìpín obìnrin méjì. Allāhu ń ṣe àlàyé fun yín kí ẹ má baà ṣìnà. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

Oúnjẹ

Surah 5

[1] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú àwọn àdéhùn ṣẹ. Wọ́n ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fun yín àfi èyí tí wọ́n bá ń kà fun yín (ní èèwọ̀), láì níí sọ ìdọdẹ ẹranko di ẹ̀tọ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ìdájọ́ ohun tí Ó bá fẹ́

[2] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe rú òfin àwọn n̄ǹkan àríṣàmì tí Allāhu gbé kalẹ̀ fún ẹ̀sìn Rẹ̀. Ẹ má ṣe sọ oṣù ọ̀wọ̀ di ẹ̀tọ́ (fún ogun ẹ̀sìn), Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn t’ó ń gbèrò láti lọ sí Ilé Haram, tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Tí ẹ bá sì ti túra sílẹ̀ nínú aṣọ hurumi, nígbà náà ẹ (lè) dọdẹ (ẹranko). Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti tayọ ẹnu-àlà nítorí pé wọ́n ṣe yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-àlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà

[3] A ṣe é ní èèwọ̀ fun yín ẹran òkúǹbete, àti ẹ̀jẹ̀, àti ẹran ẹlẹ́dẹ̀, àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tí kì í ṣe Allāhu, àti ẹran tí wọ́n fún lọ́rùn pa, àti ẹran tí wọ́n lù pa, àti ẹran tí ó ré lulẹ̀ kú, àti ẹran tí wọ́n kàn pa àti èyí tí ẹranko abìjàwàrà jẹ kù àfi èyí tí ẹ bá rí dú (ṣíwájú kí ó tó kú) àti èyí tí wọ́n pa sídìí òrìṣà. Èèwọ̀ sì ni fun yín láti yẹṣẹ́ wò. Ìwọ̀nyí ni ìbàjẹ́. Lónìí ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sọ̀rètí nù nípa ẹ̀sìn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi. Mo parí ẹ̀sìn yín fun yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fun yín. Mo sì yọ́nú sí ’Islām ní ẹ̀sìn fun yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá kó sínú ìnira ebi (láti jẹ ẹran èèwọ̀), yàtọ̀ sí olùfínnúfíndọ̀-dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[4] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè pé: "Kí ni Wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn?" Sọ pé: “Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fun yín àti (ẹran tí ẹ pa nípasẹ̀) èyí tí ẹ kọ́ ní ẹ̀kọ́ (ìdọdẹ) nínú àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ń dọdẹ. Ẹ kọ́ àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ ìdọdẹ, kí ẹ kọ́ wọn nínú ohun tí Allāhu fi mọ̀ yín. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá pa fun yín, kí ẹ sì ṣe bismillāh sí i . Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́

[5] Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fun yín lónìí. Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fun yín.1 Oúnjẹ tiyín náà, ẹ̀tọ́ ni fún wọn. (Ẹ̀tọ́ ni fun yín láti fẹ́) àwọn olómìnira nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin àti àwọn olómìnira lóbìnrin nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín, nígbà tí ẹ bá ti fún wọn ní ṣọ̀daàkí wọn; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ (bí ’Islām ṣe ní kí ẹ fẹ́ ìyàwó), láì níí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì) láì sì níí yàn wọ́n lálè.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí ìgbàgbọ́ òdodo, iṣẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò. òrìṣà ìbẹ̀rẹ̀ àti ìdáwọ́lé kan tí àwọn òyìnbó abọ̀rìṣà ń pè ní Janus ni wọ́n fi gbé oṣù àti ọdún January kalẹ̀. Àwọn kristiẹni sì tẹ́wọ́ gbà á lọ́wọ́ wọn. Mùsùlùmí yó sì máa jẹ́ mùsùlùmí lórí gbígba ọ̀rọ̀ Allāhu gbọ́ ní òdodo. Tí irú mùsùlùmí yìí bá tún wá bá àwọn kristiẹni dá sí ọdún January láì sì ṣíjú wo àwọn ewu ńlá tí kò ṣe é jànìyàn t’ó tún rọ̀ mọ́ ìgbéyàwó. Dandan sì ni fún wa láti lo āyah papọ̀ mọ́ra wọn ní ọ̀nà tí kò fi níí já sí pé mùsùlùmí tẹ̀lé ìtúmọ̀ ojú-ọ̀rọ̀ nìkan ní ìyapa sí ìtúmọ̀ ojú ọ̀rọ̀ mìíràn. Ní àkọ́kọ́ ná nínú sūrah al-Baƙọrah

[6] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì. Tí ẹ bá ní jánnábà lára, ẹ wẹ ìwẹ̀ ìmọ́ra. Tí ẹ bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ẹ̀ ń bẹ lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ilé ìgbọ̀nsẹ̀, tàbí ẹ súnmọ́ obìnrin, tí ẹ ò bá rí omi, nígbà náà kí ẹ fi erùpẹ̀ mímọ́ ṣe tayamọmu. Ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín lára rẹ̀. Allāhu kò fẹ́ láti kó wàhálà ba yín, ṣùgbọ́n Ó fẹ́ láti fọ̀ yín mọ́. Ó sì fẹ́ ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́

[7] Ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fun yín àti àdéhùn Rẹ̀, èyí tí Ó ba yín ṣe, nígbà tí ẹ̀yin sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e.” Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[8] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí ti Allāhu ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí òdodo nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti má ṣe déédé. Ẹ ṣe déédé, òhun l’ó súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[9] Allāhu ṣe àdéhùn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere (pé) àforíjìn àti ẹ̀san ńlá ń bẹ fún wọn

[10] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ní èrò inú iná Jẹhīm

[11] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fun yín; nígbà tí ìjọ kan gbèrò láti nawọ́ ìjà si yín, (Allāhu) sì kó wọn lọ́wọ́ rọ̀ fun yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Àti pé Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé

[12] Dájúdájú Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì gbé ìjòyè méjìlá dìde nínú wọn. Allāhu sì sọ fún wọn pé: “Dájúdájú Mò ń bẹ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá ń kírun, tí ẹ̀ bá ń yọ Zakāh, tí ẹ bá ń gba àwọn Òjíṣẹ́ Mi gbọ́, tí ẹ bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́, tí ẹ bá ń yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára. Dájúdájú Mo máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́. Dájúdájú Mo máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìyẹn nínú yín, ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà.”

[13] Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn ni A fi ṣẹ́bi lé wọn. A sì mú ọkàn wọn le koko (nítorí pé) wọ́n ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínú oore tí A fi ṣe ìrántí fún wọn. O ò níí yé rí oníjàǹbá láààrin wọn àfi díẹ̀ nínú wọn. Nítorí náà, ṣe àmójúkúrò fún wọn, kí o sì forí jìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere

[14] Àti pé lọ́dọ̀ àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú nasara ni àwa.”, A gba àdéhùn lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì gbàgbé ìpín kan nínú oore tí A fi ṣe ìrántí fún wọn. Nítorí náà, A gbin ọ̀tá àti ọ̀tẹ̀ sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Láìpẹ́ Allāhu máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[15] Ẹ̀yin ahlul-kitāb, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti wá ba yín. Ó ń ṣàlàyé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí ẹ fi pamọ́ nínú tírà fun yín. Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀. Ìmọ́lẹ̀ àti Tírà t’ó yanjú kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Allāhu

[16] Allāhu ń fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìmọ̀nà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àwọn n̄ǹkan) tí Allāhu yọ́nú sí, àwọn ọ̀nà àlàáfíà. (Allāhu) yó sì mú wọn jáde láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ó sì máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà (’Islām)

[17] Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Sọ pé: “Ta sì l’ó ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu tí (Allāhu) bá fẹ́ pa Mọsīh ọmọ Mọryam, àti ìyá rẹ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé run pátápátá?” Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. (Allāhu) ń ṣẹ́dàá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[18] Àwọn yẹhudi àti nasara wí pé: "Àwa ni ọmọ Allāhu àti olólùfẹ́ Rẹ̀." Sọ pé: “Kí ni ìdí tí Ó ṣe ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín nígbà náà?” Rárá (kò rí bí ẹ ṣe wí, àmọ́) abara ni yín nínú àwọn tí Ó ṣẹ̀dá. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[19] Ẹ̀yin ahlul-kitāb, dájúdájú Òjíṣẹ́ Wa ti dé ba yín, tí ó ń ṣe àlàyé (ọ̀rọ̀) fun yín lẹ́yìn àsìkò tí A ti dá àwọn Òjísẹ́ dúró, nítorí kí ẹ má baà wí pé: “Kò sí oníròó ìdùnnú tàbí olùkìlọ̀ kan tí ó dé bá wa.” Nítorí náà, dájúdájú oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ kan ti dé ba yín. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[20] Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fun yín, nígbà tí Ó fi àwọn Ànábì sáààrin yín, tí Ó ṣe yín ní ọba, tí Ó tún fun yín ní n̄ǹkan tí kò fún ẹnì kan rí ní àgbáyé (lásìkò tiyín)

[21] Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọ orí ilẹ̀ mímọ́ tí Allāhu kọ mọ́ yín. Ẹ má se padà sẹ́yìn, nítorí kí ẹ má baà padà di ẹni òfò

[22] Wọ́n wí pé: "Mūsā, dájúdájú ìjọ ajẹni-nípá wà nínú ìlú náà. Dájúdájú àwa kò sì níí wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi jáde kúrò nínú rẹ̀. Tí wọ́n bá jáde kúrò nínú rẹ̀, àwa máa wọ inú rẹ̀ nígbà náà

[23] Àwọn ọkùnrin méjì kan nínú àwọn tí ń páyà (Allāhu) - Allāhu sì kẹ́ àwọn méjèèjì - wọ́n sọ pé: "Ẹ gba ẹnu bodè wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n. Tí ẹ bá wọ inú ìlú tọ̀ wọ́n, dájúdájú ẹ máa borí wọn. Allāhu sì ni kí ẹ gbáralé, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[24] Wọ́n wí pé: "Ìwọ Mūsā, dájúdájú àwa kò níí wọ inú ìlú náà láéláé níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá sì wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, kí ìwọ àti Olúwa rẹ lọ. Kí ẹ̀yin méjèèjì jà wọ́n lógun. Dájúdájú ibí yìí ni àwa yóò jókòó sí ná

[25] Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ẹnì kan bí kò ṣe (lórí) ara mi àti arákùnrin mi. Nítorí náà, ya àwa àti ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

[26] (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ó ti di èèwọ̀ fún wọn (láti wọ inú ìlú náà) fún ogójì ọdún tí wọn yóò fi máa rìn rìn rìn lórí ilẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”

[27] Ka ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam méjèèjì fún wọn pẹ̀lú òdodo. (Rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ṣe ìtọrẹ àsè (láti fi súnmọ́ Allāhu). Wọ́n gba ti ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì, Wọn kò sì gba ti ìkejì. (Ẹni tí Wọn kò gba tirẹ̀) wí pé: “Dájúdájú èmi yóò pa ọ́.” (Ìkejì) sì sọ pé: "(Ọrẹ) tàwọn olùbẹ̀rù nìkan ni Allāhu máa gbà

[28] Dájúdájú tí o bá na ọwọ́ rẹ sí mi láti pa mí, èmi kò sì níí na ọwọ́ mi sí ọ láti pa ọ́, nítorí pé èmi ń bẹ̀rù Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[29] Dájúdájú èmi fẹ́ kí o padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde) pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ (bí ó ṣe pa) mí àti ẹ̀ṣẹ̀ tìrẹ nítorí kí o lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èrò inú Iná. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí

[30] Ẹ̀mí rẹ̀ sì gbà fún un láti pa arákùnrin rẹ̀. Ó pa á. Ó sì di ọ̀kan nínú àwọn ẹni òfò

[31] Allāhu sì gbé ẹyẹ kannakánná kan dìde. Ó sì ń fi ẹsẹ̀ wa ilẹ̀ nítorí kí ó lè fi bí ó ṣe máa bo òkú arákùnrin rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀ hàn án. Ó wí pé: “Tèmi bàjẹ́ o! Mo kágara láti dà bí irú ẹyẹ kannakánná yìí, kí n̄g sì lè bo òkú arákùnrin mi mọ́lẹ̀.” Ó sì di ara àwọn alábàámọ̀

[32] Nítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀, ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì ti wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn lẹ́yìn ìyẹn ni alákọyọ lórí ilẹ̀

[33] Ẹ̀san àwọn t’ó ń gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ni pé, kí ẹ pa wọ́n tàbí kí ẹ kàn wọ́n mọ́ igi àgbélébùú tàbí kí ẹ gé ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn ní ìpasípayọ tàbí kí ẹ lé wọn kúrò nínú ìlú. Ìyẹn ni ìyẹpẹrẹ fún wọn nílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run

[34] Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà ṣíwájú kí ẹ tó lágbára lórí wọn. Nítorí náà, ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[35] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wá àtẹ̀gùn sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (pẹ̀lú iṣẹ́ rere). Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè

[36] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá jẹ́ tiwọn àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti fi gba ara wọn sílẹ̀ níbi ìyà Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí gbà á ní ọwọ́ wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[37] Wọn yóò fẹ́ jáde kúrò nínú Iná, wọn kò sì níí lè jáde kúrò nínú rẹ̀. Ìyà gbére sì wà fún wọn

[38] Olè lọ́kùnrin àti olè lóbìnrin, ẹ gé ọwọ́ àwọn méjèèjì. (Ó jẹ́) ẹ̀san fún iṣẹ́ ọwọ́ àwọn méjèèjì. (Ó sì jẹ́) ìjìyà láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[39] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà lẹ́yìn àbòsí (ọwọ́) rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláàánú

[40] Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì máa forí jin ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[41] Ìwọ Òjíṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó bà ọ́ nínú jẹ́ àwọn t’ó ń yára lọ sínú àìgbàgbọ́ nínú àwọn t’ó fi ẹnu ara wọn wí pé: “A gbàgbọ́.” – tí ọkàn wọn kò sì gbàgbọ́ ní òdodo - àti àwọn t’ó di yẹhudi, tí wọ́n ń tẹ́tí sí irọ́, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn mìíràn tí kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, tí wọ́n ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “Tí wọ́n bá fun yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fun yín ẹ ṣọ́ra.” Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fòòró rẹ̀, o ò ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu fún un. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu kò fẹ́ fọ ọkàn wọn mọ́. Ìdójútì ń bẹ fún wọn ní ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run

[42] Wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ irọ́, wọ́n sì ń jẹ n̄ǹkan èèwọ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá wá bá ọ, ṣèdájọ́ láààrin wọn tàbí kí o ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn kò lè kó ìnira kan kan bá ọ. Tí o bá sì fẹ́ dájọ́, ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn onídéédé

[43] Báwo ni wọ́n á ṣe fi ọ́ ṣe adájọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé Taorāh wà lọ́dọ̀ wọn. Ìdájọ́ Allāhu sì wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n ń pẹ̀yìn dà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í sì ṣe onígbàgbọ́ òdodo

[44] Dájúdájú Àwa sọ Taorāh kalẹ̀. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ ń bẹ nínú rẹ̀. Àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí ń fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn t’ó di yẹhudi. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin (ń fi ṣe ìdájọ́) nítorí ohun tí A ní kí wọ́n ṣọ́ nínú tírà Allāhu. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe páyà ènìyàn. Ẹ páyà Mi. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó kékeré. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni aláìgbàgbọ́

[45] A sì ṣe é ní òfin sínú rẹ̀ pé dájúdájú ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, imú fún imú, etí fún etí àti eyín fún eyín. Òfin ẹ̀san gbígbà sì wà fún ojú-ọgbẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sí yọ̀ǹda ìgbẹ̀san, ó sì máa jẹ́ ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fún un. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí

[46] A fi ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé orípa wọn (ìyẹn, àwọn Ànábì tí wọ́n jẹ́ mùsùlùmí); tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Taorāh. A sì fún un ni ’Injīl. Ìmọ̀nà àti ìmọ́lẹ̀ wà nínú rẹ̀, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Taorāh. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu ní àsìkò tirẹ̀)

[47] Kí àwọn tí A fún ní ’Injīl ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́

[48] A sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú Tírà. Ó ń wá ààbò fún àwọn òfin inú rẹ̀. Nítorí náà, fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ dájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn t’ó yapa sí ohun tí ó dé bá ọ nínú òdodo. Olúkùlùkù nínú yín ni A ti ṣe òfin àti ìlànà fún. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fun yín ni. Nítorí náà, ẹ gbawájú níbi iṣẹ́ rere. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Ó sì máa fun yín ní ìró nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí

[49] Àti pé kí o fi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Ṣọ́ra fún wọn kí wọ́n má baà fòòró rẹ kúrò níbi apá kan ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, mọ̀ pé Allāhu kàn fẹ́ fi àdánwò kàn wọ́n ni nítorí apá kan ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àti pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ènìyàn ni òbìlẹ̀jẹ́

[50] Ṣé ìdájọ́ ìgbà àìmọ̀kan ni wọ́n ń wá ni? Ta ni ẹni tí ó dára ju Allāhu lọ níbi ìdájọ́ fún ìjọ t’ó ní àmọ̀dájú (nípa Rẹ̀)

[51] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn yẹhudi àti nasara ní ọ̀rẹ́ àyò. Apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, dájúdájú ó ti di ara wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[52] Nítorí náà, o máa rí àwọn tí àárẹ̀ wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa yára lọ sáààrin wọn. Wọn yóò máa wí pé: “À ń bẹ̀rù pé kí àpadàsí ìgbà má baà kàn wá ni.” Ó súnmọ́ kí Allāhu mú ìṣẹ́gun tàbí àṣẹ kan wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Wọn yó sì di alábàámọ̀ lórí ohun tí wọ́n fi pamọ́ sínú ọkàn wọn

[53] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: "Ṣé àwọn (yẹhudi) wọ̀nyí kọ́ ni àwọn t’ó fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé dájúdájú àwọn ń bẹ pẹ̀lú ẹ̀yin (munāfiki)?" Iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Nítorí náà, wọ́n sì di ẹni òfò

[54] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà níbi ẹ̀sìn rẹ̀ nínú yín, láìpẹ́ Allāhu máa mú àwọn ènìyàn kan wá; Ó máa nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn náà máa nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Wọn yóò rọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọn yó sì le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Wọn yóò máa jagun ẹ̀sìn fún Allāhu. Wọn kò sì níí bẹ̀rù èébú eléèébú. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbòòrò, Onímọ̀

[55] Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nìkan ni ọ̀rẹ́ yín, àwọn t’ó ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, àwọn sì ni olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun)

[56] Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọ̀rẹ́; dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùborí

[57] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn t’ó sọ ẹ̀sìn yín di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́ àti eré ṣíṣe ní ọ̀rẹ́ nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn aláìgbàgbọ́. Ẹ bẹ̀rù Allāhu tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[58] Nígbà tí ẹ bá pèpè síbi ìrun kíkí, wọn yóò sọ ọ́ di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́ àti eré ṣíṣe. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ṣe làákàyè

[59] Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ǹjẹ́ ẹ tako kiní kan lára wa bí kò ṣe pé a gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú?” Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yín ni òbìlẹ̀jẹ́

[60] Sọ pé: “Ṣé kí n̄g fun yín ní ìró àwọn tí ìyà wọn burú ju ìyẹn lọ ní ọ̀dọ̀ Allāhu?” (Òun ni) ẹni tí Allāhu ṣẹ́bi lé, tí Ó sì bínú sí, tí Ó sì sọ àwọn kan nínú wọn di ọ̀bọ, ẹlẹ́dẹ̀ àti abọ̀rìṣà. Àwọn wọ̀nyẹn ni ipò wọn burú jùlọ, àwọn sì ni wọ́n ṣìnà jùlọ

[61] Nígbà tí wọ́n bá wá sí ọ̀dọ̀ yín, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Dájúdájú wọ́n wọlé (tì yín) pẹ̀lú àìgbàgbọ́, wọ́n sì ti jáde pẹ̀lú rẹ̀. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́

[62] O máa rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn, tí wọ́n ń yára kó sínú ẹ̀ṣẹ̀, ìtayọ ẹnu-àlà àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú. Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú

[63] Kí ni kò jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn amòfin máa kọ̀ fún wọn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ owó èrú! Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú

[64] Àwọn yẹhudi wí pé: "Ọwọ́ Allāhu wà ní dídì pa." A di ọwọ́ wọn pa. A sì ṣẹ́bi lé wọn nítorí ohun tí wọ́n wí. Àmọ́ ọwọ́ Rẹ̀ méjèèjì wà ní títẹ́ sílẹ̀. Ó sì ń tọrẹ bí Ó ṣe fẹ́. Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ̀ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. A sì ju ọ̀tá àti ìkórira sáààrin wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá dáná ogun, Allāhu sì máa paná rẹ̀. Wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́

[65] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ ní òdodo, kí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), Àwa ìbá pa àwọn àìda wọn rẹ́ fún wọn, Àwa ìbá sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

[66] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn (ìyẹn, al-Ƙur’ān), wọn ìbá máa jẹ láti òkè wọn àti láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn. Ìjọ kan ń bẹ nínú wọn t’ó dúró déédé, (àmọ́) ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ń ṣe níṣẹ́ burú

[67] Ìwọ Òjíṣẹ́, fi gbogbo ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ jíṣẹ́. Tí o ò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, o ò jíṣẹ́ pé. Allāhu yó sì dáàbò bò ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ (láti ṣe ọ́ ní aburú)

[68] Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ ò rí kiní kan ṣe (nínú ẹ̀sìn) títí ẹ máa fi lo at-Taorāh àti al-’Injīl àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín (ìyẹn, al-Ƙur’ān).” Ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Rẹ yóò kúkú jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn lékún ní ìgbéraga àti àìgbàgbọ́ ni. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ aláìgbàgbọ́

[69] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn t’ó di yẹhudi, - àwọn sọ̄bi’ūn àti àwọn kristiẹni, - ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, tí ó sì ṣiṣẹ́ rere, kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́

[70] A kúkú gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. A sì rán àwọn Òjíṣẹ́ kan sí wọn. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ kan bá dé bá wọn pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí wọn kò fẹ́, wọ́n pe igun kan ní òpùrọ́, wọ́n sì ń pa igun kan

[71] Wọ́n sì lérò pé kò níí sí ìfòòró; wọ́n fọ́jú, wọ́n sì dití (sí òdodo). Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ́jú, wọ́n tún dití (sí òdodo); ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn (ló ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[72] Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu, Òun ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Mọsīh sì sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bá Allāhu wá akẹgbẹ́, Allāhu ti ṣe Ọgbà Ìdẹ̀ra ní èèwọ̀ fún un. Iná sì ni ibùgbé rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí

[73] Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Ìkẹta (àwọn) mẹ́ta.” Kò sì sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Tí wọn kò bá jáwọ́ níbi ohun tí wọ́n ń wí, dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro l’ó máa jẹ àwọn t’ó di kèfèrí nínú wọn

[74] Nítorí náà, ṣé wọn kò níí ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, kí wọ́n sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[75] Kí ni Mọsīh bí kò ṣe Òjíṣẹ́ kan. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti lọ ṣíwájú rẹ̀. Olódodo sì ni ìyá rẹ̀. Àwọn méjèèjì máa ń jẹ oúnjẹ. Wo bí A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà. Lẹ́yìn náà, wo bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo

[76] Sọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò ní ìkápá ìnira àti àǹfààní kan fun yín? Allāhu, Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”

[77] Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà nínú ẹ̀sìn yín, tí kì í ṣe (ẹ̀sìn) òdodo. Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú ìjọ kan t’ó ti ṣìnà ṣíwájú (ìyẹn, àwọn yẹhudi). Wọ́n ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́nà. Wọ́n sì ṣìnà kúrò ní ojú ọ̀nà tààrà

[78] A ṣẹ́bi lé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lórí ahọ́n (Ànábì) Dāwūd àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-àlà

[79] Wọn kì í kọ ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ láààrin ara wọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì burú

[80] O máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn t’ó ń ṣọ̀rẹ́ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Ohun tí ẹ̀mí wọn tì síwájú fún wọn sì burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Allāhu fi bínú sí wọn. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Ìyà

[81] Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, wọn kò níí mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ni òbìlẹ̀jẹ́

[82] Dájúdájú o máa rí i pé àwọn ènìyàn tí ọ̀tá wọn le jùlọ sí àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ni àwọn yẹhudi àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Dájúdájú o sì máa rí i pé àwọn ènìyàn t’ó súnmọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo jùlọ ní ìfẹ́ ni àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú nasara ni àwa.” Ìyẹn nítorí pé àwọn àlùfáà àti olùfọkànsìn ń bẹ láààrin wọn. Àti pé dájúdáju wọn kò níí ṣègbéraga (sí òdodo)

[83] Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ náà, o máa rí ẹyinjú wọn tí ó máa damije nítorí ohun tí wọ́n ti mọ̀ nínú òdodo. Wọ́n á sì sọ pé: "Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo, kọ wá mọ́ ara àwọn olùjẹ́rìí (òdodo)

[84] Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ tí a ò fi níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí ó dé bá wa nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān), tí a sì ń jẹ̀rankàn pé kí Olúwa fi wá sínú àwọn ẹni-ire

[85] Nítorí náà, nítorí ohun tí wọ́n sọ, Allāhu san wọ́n ní ẹ̀san pẹ̀lú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún àwọn olùṣe-rere

[86] Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm

[87] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe sọ àwọn n̄ǹkan dáadáa tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fun yín di èèwọ̀. Ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-àlà. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn olùtayọ ẹnu-àlà

[88] Ẹ jẹ n̄ǹkan ẹ̀tọ́ t’ó dára nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fun yín. Àti pé ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú Rẹ̀

[89] Allāhu kò níí fí ìbúra tí ó bọ́ lẹ́nu yín bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi àwọn ìbúra tí ẹ fínnúfíndọ̀ mú wá bi yín. Nítorí náà, ìtánràn rẹ̀ ni bíbọ́ tálíkà mẹ́wàá pẹ̀lú oúnjẹ tí ó wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì tí ẹ̀ ń fi bọ́ ará ilé yín, tàbí kí ẹ raṣọ fún wọn, tàbí kí ẹ tú ẹrú onígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹnikẹ́ni tí kò bá rí (èyí ṣe), ó máa gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta. Ìyẹn ni ìtánràn ìbúra yín nígbà tí ẹ bá búra. Ẹ ṣọ́ ìbúra yín. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́

[90] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọtí, tẹ́tẹ́, àwọn òrìṣà àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò, ẹ̀gbin nínú iṣẹ́ Èṣù ni. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí i nítorí kí ẹ lè jèrè

[91] Ohun tí Èṣù ń fẹ́ ni pé ó máa dá ọ̀tá àti ìkórira sílẹ̀ láààrin yín níbi ọtí àti tẹ́tẹ́. Ó sì fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi ìrántí Allāhu àti níbi ìrun kíkí. Ṣé ẹ̀yin kò níí jáwọ́ (níbi iṣẹ́ Èṣù) ni

[92] Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu, ẹ tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Kí ẹ sì ṣọ́ra. Nítorí náà, tí ẹ bá gbúnrí, kí ẹ mọ̀ pé iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé lojúṣe àwọn Òjíṣẹ́ Wa

[93] Kò sí ìbáwí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere nípa ohun tí wọ́n jẹ (nínú ouńjẹ ṣíwájú òfin) nígbà tí wọ́n bá ti bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ́rù Allāhu, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere

[94] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú Allāhu yóò fi kiní kan dan yín wò níbi ẹran-ìgbẹ́ tí ọwọ́ yín àti ọ̀kọ̀ yín bà (nínú aṣọ hurumi) nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni t’ó ń páyà Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-àlà lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un

[95] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe pa ẹran-ìgbẹ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mọ̀ọ́mọ̀ pa á nínú yín, ìtánràn rẹ̀ ni (pé ó máa pa) irú ohun tí ó pa nínú ẹran ọ̀sìn. Àwọn onídéédé méjì nínú yín l’ó sì máa ṣe ìdájọ́ (òṣùwọ̀n) rẹ̀ (fún un. Ó jẹ́) ẹran ìtánràn tí ó máa mú dé Kaaba. Tàbí kí ó fi bíbọ́ àwọn tálíkà ṣe ìtánràn. Tàbí ààrọ̀ ìyẹn ni ààwẹ̀, nítorí kí ó lè tọ́ bí ọ̀ràn rẹ̀ ṣe lágbára tó wò. Allāhu ti mójú kúrò níbi ohun t’ó ré kọjá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún padà (mọ̀ọ́mọ̀ dọdẹ nínú aṣọ hurumi), Allāhu yóò gbẹ̀san lára rẹ̀ rẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san

[96] Wọ́n ṣe odò dídẹ àti jíjẹ oúnjẹ (òkúǹbete) inú rẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fun yín. N̄ǹkan ìgbádùn ni fún ẹ̀yin àti àwọn onírìn-àjò. Wọ́n sì ṣe ìgbẹ́ dídẹ ní èèwọ̀ fun yín nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọ́n máa ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[97] Allāhu ṣe Kaaba, Ilé Haram, ní àyè ààbò fún àwọn ènìyàn. (N̄ǹkan ààbò náà ni) àwọn oṣù ọ̀wọ̀, àwọn ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[98] Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[99] Kò sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ náà bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́. Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́

[100] Sọ pé: “Ohun burúkú àti ohun dáadáa kò dọ́gba, púpọ̀ ohun burúkú ìbáà jọ ọ́ lójú”. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, ẹ̀yin onílàákàyè, nítorí kí ẹ lè jèrè.”

[101] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe máa bèèrè nípa àwọn n̄ǹkan sá. Tí A bá fi hàn yín, ó máa kó ìpalára ba yín. Tí ẹ bá sì bèèrè nípa (àwọn n̄ǹkan t’ó yẹ láti bèèrè nípa ẹ̀sìn) nígbà tí À ń sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ lọ́wọ́, A máa fi hàn yín. Allāhu ti ṣe àmójúkúrò nípa rẹ̀. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà

[102] Ìjọ kan kúkú ti bèèrè rẹ̀ ṣíwájú yín. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì di aláìgbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀

[103] Allāhu kò fi ẹran bahīrah, ẹran sā’ibah, ẹran wasīlah àti ẹran hām lọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè

[104] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. (Ẹ máa bọ̀ wá) sí ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ náà.” Wọ́n á wí pé: “Ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ti tó wa.” Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò nímọ̀ kan kan, tí wọn kò sì mọ̀nà

[105] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀nà. Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí gbogbo yín pátápátá. Nígbà náà, Ó máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[106] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, (ẹ wá) ẹ̀rí jíjẹ́ láààrin yín nígbà tí (ìpọ́kàkà) ikú bá dé bá ẹnì kan nínú yín tí ó fẹ́ sọ àsọọ́lẹ̀. (Ẹ wá) onídéédé méjì nínú yín. Tàbí àwọn méjì mìíràn yàtọ̀ si yín tí ẹ̀yin bá wà lórí ìrìn-àjò tí àjálù ikú bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ si yín. Ẹ dá àwọn méjèèjì dúró lẹ́yìn ìrun, kí wọ́n fi Allāhu búra, tí ẹ bá ṣeyèméjì (sí òdodo wọn, kí wọ́n sì sọ pé:) "A ò níí ta ìbúra wa ní iye kan kan, kódà kó jẹ́ ẹbí. A ò sì níí fi ẹ̀rí jíjẹ́ tí Allāhu (pa láṣẹ) pamọ́. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú àwa wà nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

[107] Tí wọ́n bá sì rí i pé àwọn méjèèjì dá ẹ̀ṣẹ̀ (nípa yíyí àsọọ́lẹ̀ padà), kí àwọn méjì mìíràn nínú àwọn tí àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ ṣe àbósí sí (ìyẹn, ẹbí òkú) rọ́pò wọn. Kí àwọn náà sì fi Allāhu búra pé: "Dájúdájú ẹ̀rí jíjẹ́ tiwa jẹ́ òdodo ju ẹ̀rí jíjẹ́ ti àwọn méjèèjì (àkọ́kọ́). A ò sì níí tayọ ẹnu-àlà. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú a ti wà nínú àwọn alábòsí

[108] Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ẹ̀rí jíjẹ́ wá ní ojú-pọ̀nnà rẹ̀ tàbí láti (lè là nínú) ìpáyà pé wọ́n yóò da ìbúra kan nù lẹ́yìn ìbúra tiwọn. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gbọ́ràn. Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[109] Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò kó àwọn Òjíṣẹ́ jọ, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni èsì tí wọ́n fun yín?” Wọ́n á sọ pé: “Kò sí ìmọ̀ kan fún wa (nípa rẹ̀). Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀.”

[110] (Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, rántí ìdẹ̀ra Mi lórí rẹ àti lórí ìyá rẹ, nígbà tí Mo fi ẹ̀mí Mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ràn ọ́ lọ́wọ́, tí o sì ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tí o dàgbà. (Rántí) nígbà tí Mo fún ọ ní ìmọ̀ Tírà, ìjìnlẹ̀ òye, at-Taorāh àti al-’Injīl. (Rántí) nígbà tí ò ń mọ n̄ǹkan láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ, tí ò ń fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, tí ó ń di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. Ò ń wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda. (Rántí) nígbà tí ò ń mú àwọn òkú jáde (ní alààyè láti inú sàréè) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí Mo kó àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́ ró, nígbà tí o mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”

[111] (Rántí) nígbà tí Mo fi mọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ nínú ọkàn wọn pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Èmi àti Òjíṣẹ́ Mi. Wọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.”

[112] (Rántí) nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ǹjẹ́ Olúwa rẹ lè sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ láti sánmọ̀?” Ó sọ pé: "Ẹ bẹ̀rù Allāhu tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[113] Wọ́n sọ pé: “A fẹ́ jẹ nínú rẹ̀, a sì fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, kí á sì lè mọ̀ pé o ti sọ òdodo fún wa. A sì máa wà nínú àwọn olùjẹ́rìí.”

[114] ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: "Allāhu, Olúwa wa, sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ fún wa láti inú sánmọ̀, kí ó jẹ́ ọdún fún ẹni àkọ́kọ́ wa àti ẹni ìkẹ́yìn wa.1 Kí ó sì jẹ́ àmì kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Pèsè fún wa, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùpèsè

[115] Allāhu sọ pé: “Dájúdájú Èmi yóò sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fun yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn náà nínú yín, dájúdájú Mo máa jẹ ẹ́ níyà kan tí Mi ò fi jẹ ẹnì kan rí nínú gbogbo ẹ̀dá.”

[116] (Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, ṣé ìwọ l’o sọ fún àwọn ènìyàn pé: "Ẹ mú èmi àti ìyá mi ní ọlọ́hun méjì tí ẹ óò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu?" Ó sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ọ, kò tọ́ fún mi láti sọ ohun tí èmi kò lẹ́tọ̀ọ́ (sí láti sọ). Tí mo bá sọ bẹ́ẹ̀, O kúkú ti mọ̀. O mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí mi. N̄g ò sì mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀

[117] Èmi kò sọ ohun kan fún wọn bí kò ṣe ohun tí O pa mí láṣẹ rẹ̀ pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín." Mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn níwọ̀n ìgbà tí mò ń bẹ láààrin wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí O gbà mí kúrò lọ́wọ́ wọn, Ìwọ ni Olùṣọ́ lórí wọn. Ìwọ sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan

[118] Tí O bá jẹ wọ́n níyà, dájúdájú ẹrú Rẹ ni wọ́n. Tí O bá sì forí jìn wọ́n, dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[119] Allāhu sọ pé: “Èyí ni ọjọ́ tí òdodo àwọn olódodo yóò ṣe wọ́n ní àǹfààní. Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ ń bẹ fún wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá

[120] Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú wọn. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

Ẹran ọ̀sìn

Surah 6

[1] Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó tún dá òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń bá Olúwa wọn wá akẹgbẹ́

[2] Òun ni Ẹni tí Ó da yín láti inú erùpẹ̀ amọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó fi gbèdéke ìgbà kan sí (ìṣẹ̀mí ayé yín). Àti pé gbèdéké àkókò kan (tún wà fún ayé) lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ tún ń ṣeyèméjì

[3] Òun ni Allāhu nínú àwọn sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. Ó mọ ìkọ̀kọ̀ yín àti gban̄gba yín. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[4] Kò sí àmì kan tí ó máa dé bá wọn nínú àwọn àmì Olúwa wọn, àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀

[5] Wọ́n kúkú pe òdodo nírọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, láìpẹ́ àwọn ìró ohun tí wọ́n máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn

[6] Ṣé wọn kò rí i pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? Àwọn tí A fún ní ipò lórí ilẹ̀, (irú) ipò tí A kò fún ẹ̀yin. A sì rọ omi òjò púpọ̀ fún wọn láti sánmọ̀. A sì ṣe àwọn odò tí ń ṣàn sí ìsàlẹ̀ (ilé) wọn. Lẹ́yìn náà, A pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. A sì dá àwọn ìran mìíràn lẹ́yìn wọn

[7] Tí ó bá jẹ́ pé A sọ tírà kan tí A kọ sínú tákàdá kalẹ̀ fún ọ, kí wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a mú (báyìí), dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ìbá wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”

[8] Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un?” Tí ó bá jẹ́ pé A sọ mọlāika kan kalẹ̀, ọ̀rọ̀ ìbá ti yanjú. Lẹ́yìn náà, A ò sì níí lọ́ wọn lára mọ́

[9] Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní mọlāika ni, Àwa ìbá ṣe é ní ọkùnrin. Àti pé Àwa ìbá tún fi ohun tí wọ́n ń darú mọ́ra wọn lójú rú wọn lójú

[10] Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí àwọn t’ó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po

[11] Sọ pé: “Ẹ rin orí ilẹ̀ lọ, lẹ́yìn náà kí ẹ wo báwo ni àtubọ̀tán àwọn t’ó ń pe òdodo nírọ́ ṣe rí.”

[12] Sọ pé: “Ti ta ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni.” Ó ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí. Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò níí gbàgbọ́

[13] TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó ń bẹ nínú òru àti ọ̀sán. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[14] Sọ pé: “Ṣé kí n̄g mú olùrànlọ́wọ́ kan yàtọ̀ sí Allāhu, Ẹlẹ́dàá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Òun sì ni Ó ń bọ́ (ẹ̀dá), wọn kì í bọ́ Ọ.” Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí láṣẹ pé kí n̄g jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣe ’Islām (ní àsìkò tèmi).” Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ. òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀. Èyí ni àwọn kan mọ̀ sí “ṣíṣe ìfẹ́-Ọlọ́hun”. Èwo nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni kò juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Allāhu òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀? Èwo nínú wọn sẹ́ ni kò ṣe ìfẹ́-Ọlọ́hun? Kò sí. Ìdí nìyí ti gbogbo wọn fi jẹ́ mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bi Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi rinlẹ̀ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:128-141. òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀. Àmọ́ nínú ìjọ rẹ̀ òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀

[15] Sọ pé: “Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ Ńlá, tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.”

[16] Ẹnikẹ́ni tí A bá darí rẹ̀ kúrò níbi (ìyà) ní Ọjọ́ yẹn, (Allāhu) ti ṣàánú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ pọ́nńbélé

[17] Tí Allāhu bá fi ìnira kan kàn ọ́, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun náà. Tí Ó bá sì mú oore kan bá ọ, Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[18] Òun sì ni Olùborí t’Ó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀

[19] Sọ pé: “Kí ni ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀rí?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin.” Ó sì fi ìmísí al-Ƙur’ān yìí ránṣẹ́ sí mi, nítorí kí n̄g lè fi ṣe ìkìlọ̀ fun ẹ̀yin àti ẹnikẹ́ni tí (al-Ƙur’ān) bá dé etí ìgbọ́ rẹ̀. Ṣé dájúdájú ẹ̀yin ń jẹ́rìí pé àwọn ọlọ́hun mìíràn tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.” Sọ pé: “Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Àti pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).”

[20] Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò sí níí gbàgbọ́

[21] Ta l’ó sì ṣàbòsí ju ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí (ẹni tí) ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè

[22] Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn t’ó bá (Allāhu) wá akẹgbẹ́ pé: “Níbo ni àwọn òrìṣà yín wà, àwọn tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ akẹgbẹ́ Allāhu?”

[23] Lẹ́yìn náà, ìfòòró wọn (lórí ìbéèrè náà) kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n á wí pé: “A fi Allāhu, Olúwa wa búra, àwa kì í ṣe ọ̀ṣẹbọ.”

[24] Wo bí wọ́n ṣe parọ́ mọ́ra wọn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́

[25] Ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ọ̀dọ̀ rẹ ń bẹ nínú wọn. A sì fi èbìbò bo ọkàn wọn kí wọ́n má baà gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Tí wọ́n bá rí gbogbo àmì, wọn kò níí gbà á gbọ́ débi pé nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ, wọn yó sì máa bá ọ jiyàn; àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì máa wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

[26] Àwọn ni wọ́n ń kọ̀ (fún àwọn ènìyàn láti tẹ̀lé Ànábì s.a.w.), àwọn náà sì ń takété sí i. Wọn kò sì kó ìparun bá ẹnikẹ́ni bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura

[27] Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí A bá dá wọn dúró síbi Iná, wọ́n sì máa wí pé: “Yéè! Kí wọ́n sì dá wa padà (sílé ayé), àwa kò sì níí pe àwọn āyah Olúwa wa nírọ́ (mọ́), a sì máa wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

[28] Kò rí bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ ṣíwájú ti hàn sí wọn ni. Tí ó bá jẹ́ pé A bá dá wọn padà (sílé ayé), wọn yóò kúkú padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n

[29] Wọ́n wí pé: "Kí ni (ó tún jẹ́ ìṣẹ̀mí ọ̀run) bí kò ṣe ìṣẹ̀mí wa nílé ayé; Wọn kò sì níí gbé wa dìde (ní ọ̀run)

[30] Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí wọ́n bá dá wọn dúró sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, Ó sì máa sọ pé: “Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?” Wọ́n á sì wí pé: “Rárá (òdodo ni), Olúwa wa.” (Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí pé ẹ máa ń ṣàì gbàgbọ́.”

[31] Dájúdájú àwọn t’ó pe pípàdé Allāhu (lọ́run) nírọ́ ti ṣòfò débi pé nígbà tí Àkókò náà bá dé bá wọn lójijì, wọ́n á wí pé: “A ká àbámọ̀ lórí ohun tí a fi jáfira.” Wọ́n sì máa ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn sẹ́yìn wọn. Kíyè sí i, ohun tí wọn yóò rù lẹ́ṣẹ̀ sì burú

[32] Ìṣẹ̀mí ayé kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe eré àti ìranù. Ọgbà Ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni

[33] A kúkú ti mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń wí yóò bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú wọn kò lè pè ọ́ ní òpùrọ́, ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ń tako àwọn āyah Allāhu ni

[34] Wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan lópùrọ́ ṣíwájú rẹ. Wọ́n sì ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n fi pè wọ́n ní òpùrọ́. Wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n títí di ìgbà tí àrànṣe Wa fi dé bá wọn. Kò sì sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu. Dájúdájú ìró àwọn Òjíṣẹ́ ti dé bá ọ

[35] Tí ó bá sì jẹ́ pé gbígbúnrí wọn lágbára lára rẹ, nígbà náà tí o bá lágbára láti wá ihò kan sínú (àjà) ilẹ̀, tàbí àkàbà kan sínú sánmọ̀ (ṣe bẹ́ẹ̀) kí o lè mú àmì kan wá fún wọn. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá kó wọn jọ sínú ìmọ̀nà (’Islām). Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn aláìmọ̀kan

[36] Àwọn t’ó ń gbọ́rọ̀ ni àwọn t’ó ń jẹ́pè. Àwọn òkú, Allāhu yó sì gbé wọn dìde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò dá wọn padà sí

[37] Wọ́n tún wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu lágbára láti sọ àmì kan kalẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.”

[38] Kò sí ohun abẹ̀mí kan (t’ó ń rìn) lórí ilẹ̀, tàbí ẹyẹ kan t’ó ń fò pẹ̀lú apá rẹ̀ méjèèjì bí kò ṣe àwọn ẹ̀dá kan (bí) irú yín. A kò fi kiní kan sílẹ̀ (láì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀) sínú Tírà (ìyẹn, ummul-kitāb). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni wọn yóò kó wọn jọ sí

[39] Àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, adití àti ayaya t’ó wà nínú àwọn òkùnkùn ni wọ́n. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa ṣì í lọ́nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fi sójú ọ̀nà tààrà (’Islām)

[40] Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín tàbí tí Àkókò náà bá dé ba yín, ṣe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni ẹ̀yin máa pè, tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[41] Rárá, Òun (nìkan) l’ẹ̀ ń pè. Ó sì máa mú (ìnira) tí ẹ̀ ń pè É sí kúrò (fun yín), tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin yó sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ sí I

[42] Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. A sì fi ìpọ́njú àti àìlera gbá wọn mú nítorí kí wọ́n lè rawọ́ rasẹ̀ (sí Allāhu)

[43] Wọn kò ṣe rawọ́ rasẹ̀ (sí Wa) nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn! Ṣùgbọ́n ọkàn wọn ti le koko. Èṣù sì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn

[44] Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbàgbé ohun tí A fi ṣe ìrántí fún wọn, A ṣí àwọn ọ̀nà gbogbo n̄ǹkan sílẹ̀ fún wọn, títí di ìgbà tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ sí ohun tí A fún wọn (nínú oore ayé.), A sì mú wọn lójijì. Wọ́n sì di olùsọ̀rètínù

[45] Nítorí náà, A pa ìjọ t’ó ṣàbòsí run pátápátá. Gbogbo ọpẹ́ sì ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[46] Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá gba ìgbọ́rọ̀ yín àti ìríran yín, tí Ó sì di ọkàn yín pa, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu ni ó máa mú un wá fun yín? Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì ń gbúnrí

[47] Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín ní òjijì tàbí ní ojúkojú, ṣé wọ́n máa pa ẹnì kan run bí kò ṣe ìjọ alábòsí!”

[48] A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ náà níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí wọ́n jẹ́) oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ rẹ̀), kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́

[49] Àwọn t’ó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, ọwọ́ ìyà yóò tẹ̀ wọ́n nítorí pé wọ́n máa ń ṣèbàjẹ́

[50] Sọ pé: “Èmi kò sọ fun yín pé àwọn ilé-owó Allāhu wà lọ́dọ̀ mi, èmi kò sì nímọ̀ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ fun yín pé mọlāika kan ni mí. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí.” Sọ pé: "Ǹjẹ́ afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Ṣé ẹ ò ronú jinlẹ̀ ni

[51] Fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn t’ó ń páyà pé Wọ́n máa kó àwọn jọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, kò sì níí sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. (Kìlọ̀ fún wọn) kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu)

[52] Má ṣe lé àwọn t’ó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí

[53] Báyẹn ni A ṣe fi apá kan wọn ṣe àdánwò fún apá kan nítorí kí (àwọn aláìgbàgbọ́) lè wí pé: “Ṣé àwọn (mùsùlùmí aláìní) wọ̀nyí náà ni Allāhu ṣe ìdẹ̀ra (ìmọ̀nà) fún láààrin wa!?” Ṣé Allāhu kọ́ l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùdúpẹ́ ni

[54] Nígbà tí àwọn t’ó gba àwọn āyah Wa gbọ́ bá wá bá ọ, sọ (fún wọn) pé: "Kí àlàáfíà máa ba yín. Olúwa yín ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí ó ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[55] Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah nítorí kí ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè fojú hàn kedere

[56] Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi láti jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu.” Sọ pé: “Èmi kò níí tẹ̀lé ìfẹ́-inú yín. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, mo ti ṣìnà (tí mo bá tẹ̀lé ìfẹ́-inú yín). Èmi kò sì sí nínú àwọn olùmọ̀nà.”

[57] Sọ pé: “Dájúdájú mo wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, ẹ̀yin sì pè é nírọ́. Kò sí ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ní ọ̀dọ̀ mi. Kò sí ìdájọ́ náà (fún ẹnikẹ́ni) àyàfi fún Allāhu, Ẹni tí ń sọ (ìdájọ́) òdodo. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.”

[58] Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi ni, Wọn ìbá ti ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà láààrin èmi àti ẹ̀yin. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn alábòsí.”

[59] Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkọ̀kọ̀ wà. Kò sí ẹni t’ó nímọ̀ rẹ̀ àfi Òun. Ó nímọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ àti odò. Ewé kan kò sì níí já bọ́ àfi kí Ó nímọ̀ rẹ̀. Kò sì sí kóró èso kan nínú òkùnkùn (inú) ilẹ̀, kò sí ohun tútù tàbí gbígbẹ kan àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú

[60] Òun ni Ẹni t’Ó ń kùn yín ní oorun ní alẹ́. Ó sì nímọ̀ nípa ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́ ní ọ̀sán. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbe yín dìde (fún ìjẹ-ìmu) ní (ọ̀sán) nítorí kí wọ́n lè parí gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí yín. Lẹ́yìn náà, Ó máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[61] Òun ni Olùborí t’Ó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Ó sì ń rán àwọn ẹ̀ṣọ́ kan si yín títí di ìgbà tí ikú yóò fi dé bá ẹnì kọ̀ọ̀kan yín. Àwọn Òjíṣẹ́ wa yó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, wọn kò sì níí jáfira

[62] Lẹ́yìn náà, wọ́n yóò dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu, Olúwa wọn, Òdodo. Kíyè sí i, tiRẹ̀ ni ìdájọ́. Òun sì yára jùlọ nínú àwọn olùṣírò

[63] Sọ pé: “Ta ni ẹni t’ó ń gbà yín là nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò, Ẹni tí ẹ̀ ń pè pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ní ìkọ̀kọ̀ pé: "Dájúdájú tí Ó bá gbà wá là nínú èyí, dájúdájú àwa yóò wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un)

[64] Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń gbà yín là nínú rẹ̀ àti nínú gbogbo ìbànújẹ́. Lẹ́yìn náà, ẹ tún ń ṣẹbọ.”

[65] Sọ pé: “Ó lágbára láti fi ìyà ránṣẹ́ si yín láti òkè yín tàbí láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ yín, tàbí kí Ó dà yín pọ̀ mọ́ onírúurú ìjọ, nítorí kí Ó lè mu apá kan yín fìnira kan apá kan. Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè gbọ́ àgbọ́yé.”

[66] Àwọn ènìyàn rẹ pe al-Ƙur’ān nírọ́! (Àmọ́) òdodo ni. Sọ pé: “Èmi kì í ṣe olùṣọ́ lórí yín.”

[67] Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ l’ó ní àkókò (ìṣẹ̀lẹ̀). Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀

[68] Nígbà tí o bá rí àwọn t’ó ń sọ ìsọkúsọ nípa àwọn āyah Wa, nígbà náà ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn. Tí Èṣù bá ń mú ọ gbàgbé (tẹ́lẹ̀), ní báyìí lẹ́yìn ìrántí má ṣe jókòó ti ìjọ alábòsí

[69] Kiní kan nínú ìṣírò-iṣẹ́ wọn kò sí lọ́rùn àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu), ṣùgbọ́n ìṣítí ni nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún Iná)

[70] Pa àwọn t’ó sọ ẹ̀sìn wọn di eré ṣíṣe àti ìranù tì. Ìṣẹ̀mí ayé sì tàn wọ́n jẹ. Fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìṣítí nítorí kí wọ́n má baà fa ẹ̀mí kalẹ̀ sínú ìparun nípasẹ̀ ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (aburú). Kò sì sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Tí ó bá sì fi gbogbo ààrọ̀ ṣèràpadà, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fà kalẹ̀ fún ìparun nípasẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ohun mímu gbígbóná àti ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n máa ń ṣàì gbàgbọ́

[71] Sọ pé: “Ṣé a óò máa pè lẹ́yìn Allāhu, ohun tí kò lè ṣe wá ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wa; (ṣé) kí wọ́n tún dá wa padà sí ẹsẹ̀-àárọ̀ wa lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti fi ọ̀nà mọ̀ wá (kí á lè dà) bí ẹni tí Èṣù mú tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tí ìdààmú dé bá? Ó (sì) ní àwọn ọ̀rẹ́ kan tí wọ́n ń pè é síbi ìmọ̀nà (pé), “Máa bọ̀ ní ọ̀dọ̀ wa.” Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà ti Allāhu (’Islām), òhun ni ìmọ̀nà. Wọ́n sì pa wá láṣẹ pé kí á gba ẹ̀sìn ’Islām nítorí ti Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

[72] Àti pé kí ẹ kírun, kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Òun ni Ẹni tí wọ́n yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[73] Òun sì ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu máa yí ilẹ̀ àti sánmọ̀ padà sí n̄ǹkan mìíràn), Ó sì máa sọ pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. Òdodo ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀. TiRẹ̀ sì ni ìjọba ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba ni. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán

[74] (Rántí) nígbà tí ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀, Āzar, (pé): “Ṣé o máa sọ àwọn ère òrìṣà di ọlọ́hun ni? Dájúdájú èmi rí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

[75] Báyẹn ni wọ́n ṣe fi (àwọn àmì) ìjọba Allahu tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ han (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm nítorí kí ó lè wà nínú àwọn alámọ̀dájú

[76] Nígbà tí òkùnkùn alẹ́ bò ó mọ́lẹ̀, ó rí ìràwọ̀ kan, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn (olúwa) t’ó ń wọ̀ọ̀kùn.”

[77] Nígbà tí ó rí òṣùpá t’ó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Dájúdájú tí Olúwa mi kò bá tọ́ mi sọ́nà, dájúdájú mo máa wà nínú àwọn olùṣìnà ènìyàn.”

[78] Nígbà tí ó rí òòrùn t’ó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi; èyí tóbi jùlọ.” Nígbà t’ó wọ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu)

[79] Dájúdájú èmi dojú mi kọ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (mo) dúró déédé (sínú ’Islām fún Un). Èmi kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

[80] Àwọn ènìyàn rẹ̀ sì jà á níyàn. Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò jà mí níyàn nípa Allāhu, Ó sì ti fi ọ̀nà mọ̀ mí? Èmi kò sì páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Un, àfi bí Allāhu bá fẹ́ kiní kan (pé kó ṣẹlẹ̀). Olúwa mi fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni

[81] Báwo ni èmi yóò ṣe páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Allāhu, tí ẹ̀yin kò sì páyà pé ẹ̀ ń bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pẹ̀lú ohun tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fun yín lórí rẹ̀? Èwo nínú ikọ̀ méjèèjì l’ó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ẹ bá nímọ̀

[82] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọn kò sì da ìgbàgbọ́ wọn pọ̀ mọ́ àbòsí (ìbọ̀rìṣà), àwọn wọ̀nyẹn ni ìfọ̀kànbalẹ̀ ń bẹ fún. Àwọn sì ni olùmọ̀nà

[83] Ìyẹn ni àwíjàre Wa tí A fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm lórí àwọn ènìyàn rẹ̀. À ń ṣe àgbéga ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

[84] Ati pé A ta á lọ́rẹ (Ànábì) ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (tí ó jẹ́ ọmọ ’Ishāƙ). Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fi mọ̀nà. A sì fi (Ànábì) Nūh mọ̀nà ṣíwájú. Àti pé nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì ’Ibrọ̄hīm tí A fi mọ̀nà ni àwọn Ànábì) Dāwūd, Sulaemọ̄n, ’Ayyūb, Yūsuf, Mūsā àti Hārūn. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)

[85] Àti (Ànábì) Zakariyyā, Yahyā, ‘Īsā àti ’Ilyās; gbogbo wọn wà nínú àwọn ẹni rere

[86] Àti ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘, Yūnus àti Lūt; ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A ṣoore àjùlọ fún lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò wọn)

[87] Àti pé nínú àwọn bàbá wọn, àrọ́mọdọ́mọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn, A ṣà wọ́n lẹ́ṣà. A sì fi wọ́n mọ̀nà tààrà (’Islām)

[88] Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà nínú àwọn ẹrú Rẹ̀. Tí wọ́n bá fi lè ṣẹbọ ni, dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere) ìbá bàjẹ́ mọ́ wọn lọ́wọ́

[89] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A fún ní Tírà, ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah) àti (ipò) Ànábì. Nítorí náà, tí àwọn wọ̀nyí bá ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, dájúdájú A ti gbé e lé àwọn ènìyàn kan lọ́wọ́, tí wọn kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀

[90] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Nítorí náà, ọ̀nà wọn ni kí o tẹ̀lé. Sọ pé: “Èmi kò bi yín ní owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.”

[91] Wọn kò fún Allāhu ní iyì tí ó tọ́ sí I, nígbà tí wọ́n wí pé: “Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀ fún abara kan.” Sọ pé: "Ta ni Ó sọ tírà tí (Ànábì) Mūsā mú wá kalẹ̀, (èyí t’ó jẹ́) ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn, èyí tí ẹ ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé àjákọ, tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀, tí ẹ sì ń fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ rẹ̀ pamọ́, A sì fi ohun tí ẹ ò mọ̀ mọ̀ yín, ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín?" Sọ pé: "Allāhu ni." Lẹ́yìn náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìsọkúsọ wọn, kí wọ́n máa ṣeré

[92] Èyí (al-Ƙur’ān) tún ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀; ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀ àti pé nítorí kí o lè ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù). Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, wọ́n gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àwọn sì ni wọ́n ń ṣọ́ ìrun wọn

[93] Ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí ẹni tí ó wí pé wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi - A ò sì fi kiní kan ránṣẹ́ sí i - àti ẹni tí ó wí pé "Èmi náà yóò sọ irú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ kalẹ̀."? Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn alábòsí bá wà nínú ìpọ́kàkà ikú, tí àwọn mọlāika nawọ́ wọn (sí wọn pé) “Ẹ mú ẹ̀mí yín jáde wá. Lónìí ni Wọn yóò san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí ohun tí ẹ̀ máa ń sọ nípa Allāhu ní àìtọ́. Ẹ sì máa ń ṣe ìgbéraga sí àwọn āyah Rẹ̀.”

[94] Dájúdájú ẹ ti wá bá wa ní ìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ẹ sì ti fi ohun tí A fun yín sílẹ̀ sí ẹ̀yìn yín. A ò mà rí àwọn olùṣìpẹ̀ yín pẹ̀lú yín, àwọn tí ẹ sọ láì ní ẹ̀rí pé dájúdájú láààrin yín àwọn ni akẹgbẹ́ (fún Allāhu). Dájúdájú àṣepọ̀ ààrin yín ti já pátápátá. Àti pé ohun tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn (láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí ìṣìpẹ̀ yín) ti dòfo mọ yín lọ́wọ́

[95] Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú kóró èso irúgbìn àti kóró èso dàbínù hù jáde. Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú. Ó sì ń mú òkú jáde láti ara alààyè. Ìyẹn ni Allāhu. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo

[96] Ó ń mú ojúmọ́ mọ́. Ó ṣe òru ní ìsinmi. (Ó ń mú) òòrùn àti òṣùpá (rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀

[97] Òun ni Ẹni tí Ó fi àwọn ìràwọ̀ ṣe (ìmọ́lẹ̀) fun yín kí ẹ lè fi ríran nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn t’ó nímọ̀

[98] Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Nítorí náà, ibùgbé (nílé ayé) àti ibùpadàsí (ní ọ̀run wà fun yín). A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn t’ó ní àgbọ́yé

[99] Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A fi mú gbogbo n̄ǹkan ọ̀gbìn jáde. A tún mú ewéko t’ó ń dán lọ̀gbọ́lọ̀gbọ́ jáde láti inú rẹ̀. A tún ń mú ṣiri èso jáde nínú rẹ̀. (A sì ń mú jáde) láti ara igi dàbínù, láti ara èso àkọ́yọ rẹ̀, èso t’ó ṣùjọ mọ́ra wọn t’ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ wálẹ̀. (À ń ṣe) àwọn ọgbà oko èso àjàrà, èso zaetūn àti èso rummọ̄n (ní àwọn èso t’ó) jọra àti (àwọn èyí tí) kò jọra. Ẹ wo èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so àti (nígbà tí ó bá) pọ́n. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo

[100] Wọ́n sì fi àwọn àlùjànnú ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dàá wọn! Wọ́n tún parọ́ mọ́ Ọn (pé) Ó bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, láì nímọ̀ kan (nípa Rẹ̀). Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)

[101] Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni. Báwo ni Ó ṣe ní ọmọ nígbà tí kò ní aya. Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[102] Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín; kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan

[103] Àwọn ojú (ẹ̀dá) kò lè ká Allāhu. Òun sì ká àwọn ojú. Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán

[104] Àwọn ẹ̀rí t’ó dájú kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni t’ó bá ríran, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì fọ́jú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Èmi kì í ṣe olùṣọ́ lórí yín

[105] Báyẹn ni A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè wí pé: "O kẹ́kọ̀ọ́ (rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ni." Dípò kí wọ́n wí pé: "Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ ni." àti nítorí kí A lè ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn t’ó nímọ̀)

[106] Tẹ̀lé ohun tí wọ́n fi rán ọ́ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ

[107] Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ìmọ̀nà fún wọn), wọn ìbá tí ṣẹbọ. A ò sì fi ọ́ ṣe olùṣọ́ lórí wọn. Àti pé ìwọ kọ́ ni alámòjúútó wọn

[108] Ẹ má ṣe bú àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kí àwọn (abọ̀rìṣà) má baà bú Allāhu ní ti àbòsí àti àìnímọ̀. Báyẹn ni A ti ṣe iṣẹ́ ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni ibùpadàsí wọn. Nítorí náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n máa ń ṣe níṣẹ́

[109] Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé, dájúdájú tí àmì (ìyanu) kan bá dé bá àwọn, àwọn gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́. Sọ pé: "Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà." Kí sì ni ó máa mu yín fura mọ̀ pé dájúdájú nígbà tí ó bá dé (bá wọn) wọn máa gbà á gbọ́

[110] A máa yí ọkàn wọn àti ojú wọn sódì ni; (wọn kò níí gbà á gbọ́) gẹ́gẹ́ bí wọn kò ṣe gbàgbọ́ nínú (èyí t’ó ṣíwájú nínú àwọn àmì ìyanu) nígbà àkọ́kọ́. A ó sì fí wọn sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà

[111] Dájúdájú tí A bá sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wọn, tí àwọn òkú ń bá wọn sọ̀rọ̀, tí A tún kó gbogbo n̄ǹkan jọ síwájú wọn, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi tí Allāhu bá fẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni aláìmọ̀kan

[112] Báyẹn ni A ti ṣe àwọn èṣù ènìyàn àti èṣù àlùjànnú ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan; apá kan wọn ń fi odù irọ́ ránṣẹ́ sí apá kan ní ti ẹ̀tàn. Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́ (láti tọ́ wọn sọ́nà ni) wọn ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, fi wọn sílẹ̀ tòhun ti àdápa irọ́ tí wọ́n ń dá

[113] Kí àwọn ọkàn tí wọn kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ máa tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí (odù irọ́ Èṣù), kí wọ́n máa yọ́nú sí i, kí wọ́n sì máa dá ohun tí wọ́n ń dá lẹ́ṣẹ̀ ǹ só

[114] Ṣé n̄ǹkan mìíràn ni kí n̄g wá ní olùdájọ́ lẹ́yìn Allāhu ni? Òun sì ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fun yín tí wọ́n fi ṣàlàyé ìdájọ́. Àwọn tí A sì fún ní tírà mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì

[115] Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ pé ní òdodo àti ní déédé. Kò sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[116] Tí o bá tẹ̀lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀, wọ́n máa ṣì ọ́ lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọn kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Kí sì ni wọn (ń ṣe) bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́

[117] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Àti pé, Òun sì l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà

[118] Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá fi orúkọ Allāhu pa, tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Rẹ̀

[119] Kí ni ó máa kọ̀ fun yín láti jẹ nínú ohun tí wọ́n fi orúkọ Allāhu pa! Ó kúkú ti ṣàlàyé fun yín ohun tí Ó ṣe ní èèwọ̀ fun yín àyàfi èyí tí ìnira (ebi) bá tì yín débẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ni wọ́n ń fi ìfẹ́-inú wọn pẹ̀lú àìnímọ̀ (wọn) ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùtayọ ẹnu-àlà

[120] Ẹ fi èyí t’ó hàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́ nínú rẹ̀ sílẹ̀. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá lẹ́ṣẹ̀

[121] Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ jẹ nínú ohun tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa. Dájúdájú ìbàjẹ́ ni. Àti pé dájúdájú àwọn èṣù, wọn yóò máa fi ìránde odù irọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹni wọn, nítorí kí wọ́n lè takò yín. Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé wọn, dájúdájú ẹ ti di ọ̀ṣẹbọ

[122] Ǹjẹ́ ẹni tí (àfiwé rẹ̀) jẹ́ òkú (ìyẹn, aláìgbàgbọ́), tí A sọ di alààyè (nípa pé ó gba ’Islām), tí A sì fún un ní ìmọ́lẹ̀ (ìyẹn, ìmọ̀ ẹ̀sìn), tí ó sì ń lò ó láààrin àwọn ènìyàn, (ǹjẹ́) ó dà bí ẹni tí àfiwé tirẹ̀ jẹ́ (ẹni tí) ń bẹ nínú àwọn òkùnkùn (àìgbàgbọ́), tí kò sì jáde kúrò nínú rẹ̀? Báyẹn ni wọ́n ti ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn aláìgbàgbọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[123] Báyẹn ni A ṣe sọ àwọn àgbà kan di ọ̀daràn ìlú nínú ìlú kọ̀ọ̀kan, nítorí kí wọ́n lè máa dète níbẹ̀. Wọn kò sì dète sí ẹnikẹ́ni bí kò ṣe sí ara wọn, wọn kò sì fura

[124] Nígbà tí āyah kan bá sì dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Àwa kò níí gbà á gbọ́ títí di ìgbà tí wọ́n bá tó fún àwa náà ní irú ohun tí wọ́n fún àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu.” Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ibi tí Ó ń fí iṣẹ́-rírán Rẹ̀ sí. Láìpẹ́ ìyẹpẹrẹ àti ìyà líle láti ọ̀dọ̀ Allāhu yóò dé bá àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀ nítorí ohun tí wọ́n ń dá léte

[125] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fọ̀nà mọ̀, Ó máa ṣí igbá-àyà rẹ̀ payá fún ’Islām. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́ ṣì lọ́nà, Ó máa fún igbá-àyà rẹ̀ pa gádígádí bí ẹni pé ó ń gùnkè lọ sínú sánmọ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe dẹ wàhálà asán sí àwọn tí kò gbàgbọ́

[126] Èyí ni ojú ọ̀nà Olúwa rẹ (t’ó jẹ́) ọ̀nà tààrà. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó ń lo ìrántí

[127] Ilé àlàáfíà ń bẹ fun wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Òun sì ni Alátìlẹ́yìn wọn nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[128] (Rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, (Ó máa sọ pé): “Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú, dájúdájú ẹ ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sọnù.” Àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú àwọn ènìyàn yóò wí pé: “Olúwa wa, apá kan wa gbádùn apá kan ni. A sì ti lo àsìkò wa tí O bù fún wa (láti lò).” (Allāhu) sọ pé: “Iná ni ibùgbé yín; olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀ àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́ . Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

[129] Báyẹn ni A ṣe fi apá kan àwọn alábòsí ṣọ̀rẹ́ apá kan (wọn) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[130] Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, ṣé àwọn Òjíṣẹ́ kan láààrin yín kò wá ba yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Mi fun yín, tí wọ́n sì ń fi ìpàdé yín Òní yìí ṣèkìlọ̀ fun yín? Wọ́n wí pé: “A jẹ́rìí léra wa lórí (pé wọ́n wá).” Ìṣẹ́mí ayé tàn wọ́n jẹ. Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́

[131] Ìyẹn nítorí pé Olúwa rẹ kò níí pa àwọn ìlú run nípasẹ̀ àbòsí (ọwọ́ wọn), lásìkò tí àwọn ara ìlú náà jẹ́ aláìmọ̀ (títí Òjíṣẹ́ yóò fi dé bá wọn)

[132] Àwọn ipò (ìkẹ́ àti ipò ìyà) ń bẹ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ohun tí wọ́n bá ṣe níṣẹ́. Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[133] Olúwa rẹ ni Ọlọ́rọ̀, Aláàánú. Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò (lórí ilẹ̀). Ó sì máa fi ohun tí Ó bá fẹ́ rọ́pò (yín) lẹ́yìn (ìparun) yín gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe mu yín jáde lẹ́yìn (ìparun) àrọ́mọdọ́mọ àwọn ìjọ mìíràn

[134] Dájúdájú ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín, ó kúkú ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀; ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́

[135] Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ dúró sórí ọ̀nà yín, dájúdájú èmi náà yóò dúró (sórí ọ̀nà mi), láìpẹ́ ẹ̀ máa mọ ẹni tí Ọgbà (Ìdẹ̀ra) yóò jẹ́ ìkángun tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”

[136] Wọ́n sì fi ìpín kan fún Allāhu nínú ohun tí Ó dá nínú n̄ǹkan oko àti ẹran-ọ̀sìn; wọ́n wí pé: "Èyí ni ti Allāhu – pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́, - èyí sì ni ti àwọn òrìṣà wa." Nítorí náà, ohun tí ó bá jẹ́ ti àwọn òrìṣà kò níí dàpọ̀ mọ́ ti Allāhu. Ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Allāhu, ó ń dàpọ̀ mọ́ ti àwọn òrìṣà wọn; ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú

[137] Báyẹn ni àwọn òrìṣà wọn ṣe pípa àwọn ọmọ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ nítorí kí wọ́n lè pa wọ́n run àti nítorí kí wọ́n lè d’ojú ẹ̀sìn wọn rú mọ́ wọn lọ́wọ́. Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí ṣe (bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ tòhun ti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́

[138] Wọ́n tún wí pé: "Èèwọ̀ ni àwọn ẹran-ọ̀sìn àti n̄ǹkan oko wọ̀nyí. Ẹnì kan kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ àfi ẹni tí a bá fẹ́, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́." - Àwọn ẹran-ọ̀sìn kan tún ń bẹ tí wọ́n ṣe ẹ̀yìn wọn ní èèwọ̀ (fún gígùn àti ẹrù rírù), àwọn ẹran kan tún ń bẹ tí wọn kì í fi orúkọ Allāhu pa. (Wọ́n fi àwọn n̄ǹkan wọ̀nyí) dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́

[139] Wọ́n tún wí pé: "Ohun tí ń bẹ nínú ikùn àwọn ẹran-ọ̀sìn wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn ọkùnrin wa nìkan ṣoṣo, ó sì jẹ́ èèwọ̀ fún àwọn obìnrin wa." Tí ó bá sì jẹ́ òkú ọmọ-ẹran, akẹgbẹ́ sì ni wọn nínú (ìpín) rẹ̀. (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san irọ́ (ẹnu) wọn. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

[140] Àwọn t’ó fi agọ̀ àti àìmọ̀ pa àwọn ọmọ wọn kúkú ti ṣòfò; wọ́n tún ṣe ohun tí Allāhu pa lésè fún wọn ní èèwọ̀, ní ti dídá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Wọ́n kúkú ti ṣìnà, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà

[141] (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn n̄ǹkan ọgbà oko èyí tí ẹ̀ ń fọwọ́ ara yín gbìn àti èyí t’ó ń lalẹ̀ hù àti dàbínù àti irúgbìn tí (adùn) jíjẹ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn, àti èso zaetūn àti èso rummọ̄n t’ó jọra wọn àti èyí tí kò jọra wọn. Ẹ jẹ nínú èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so, kí ẹ sì yọ Zakāh rẹ̀ ní ọjọ́ ìkórè rẹ̀. Kí ẹ sì má yàpà. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn àpà

[142] Ó sì ń bẹ nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn, èyí t’ó lè ru ẹrù àti èyí tí kò lè ru ẹrù. Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fun yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù; dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín

[143] (Allāhu dá ẹran) mẹ́jọ ní takọ-tabo; méjì nínú àgùtàn (takọ-tabo), méjì nínú ewúrẹ́ (takọ-tabo). Sọ pé: "Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Ẹ fún mi ní ìró pẹ̀lú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[144] Méjì nínú ràkúnmí (takọ-tabo) àti méjì nínú màálù (takọ-tabo). Sọ pé: "Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Tàbí ṣé ẹ̀yin wà níbẹ̀ nígbà tí Allāhu pa yín láṣẹ èyí ni?" Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí t’ó tún tayọ ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu láti lè ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[145] Sọ pé: "Èmi kò rí nínú ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi tí Wọ́n ṣe jíjẹ rẹ̀ ní èèwọ̀ fún ẹni tí ó ń jẹ ẹ́ àfi ohun tí ó bá jẹ́ ẹran òkúǹbete tàbí ẹ̀jẹ̀ ṣíṣàn,1 tàbí ẹran ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé dájúdájú ẹ̀gbin ni, tàbí ẹran ìyapa (àṣẹ Allāhu) tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ t’ó yàtọ̀ sí Allāhu. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ìnira (ebi) bá mú jẹ ẹ́, yàtọ̀ sí ẹni t’ó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-àlà, dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[146] A ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn t’ó di yẹhudi gbogbo ẹran eléèékánná (tàbí onípátákò t’ó ṣùpọ̀ mọ́ra wọn). Nínú ẹran màálù àti àgùtàn, A tún ṣe ọ̀rá àwọn méjèèjì ní èèwọ̀ fún wọn àfi èyí tí ó bá lẹ̀ mọ́ ẹ̀yìn wọn tàbí ìfun tàbí èyí tí ó bá ròpọ̀ mọ́ eegun. Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí àbòsí ọwọ́ wọn. Dájúdájú Àwa sì ni Olódodo

[147] Tí wọ́n bá sì pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ nígbà náà pé: "Olúwa yín ni Oníkẹ̀ẹ́ tó gbòòrò. Kò sì sí ẹni t’ó lè gbé ìyà Rẹ̀ kúrò lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀

[148] Àwọn t’ó ń ṣẹbọ yóò wí pé: "Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni àwa àti àwọn bàbá wa ìbá tí ṣẹbọ, àti pé àwa ìbá tí ṣe n̄ǹkan kan léèwọ̀." Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́ títí wọ́n fi tọ́ ìyà Wa wò. Sọ pé: "Ǹjẹ́ ìmọ̀ kan ń bẹ ní ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ mú un jáde fún wa?" Ẹ̀yin kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Kí sì ni ẹ̀ ń sọ bí kò ṣe pé ẹ̀ ń parọ́

[149] Sọ pé: "Ti Allāhu ni ẹ̀rí t’ó pé pérépéré." Nítorí náà, tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá fi gbogbo yín mọ̀nà pátápátá

[150] Sọ pé: "Ẹ mú àwọn ẹlẹ́rìí yín jáde, àwọn t’ó máa jẹ́rìí pé dájúdájú Allāhu l’ó ṣe èyí léèwọ̀." Tí wọ́n bá jẹ́rìí (sírọ́), ìwọ má ṣe bá wọn jẹ́rìí (sí i). Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ àti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́. Àwọn sì ni wọ́n ń bá Olúwa wọn wá akẹgbẹ́

[151] Sọ pé: "Ẹ wá kí n̄g ka ohun tí Olúwa yín ṣe ní èèwọ̀ fun yín; pé kí ẹ má ṣe fí n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I, (kí ẹ sì ṣe) dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì, kí ẹ sì má ṣe pa àwọn ọmọ yín nítorí (ìbẹ̀rù) òṣì, – Àwa ni À ń pèsè fun ẹ̀yin àti àwọn – kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ àwọn ìwà ìbájẹ́ – èyí t’ó hàn nínú rẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́, - àti pé kí ẹ sì má ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fun yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè

[152] Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn àyàfi ní ọ̀nà t’ó dára jùlọ títí ó fi máa dàgbà. Ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n pé dáadáa. A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tí ẹ bá sọ̀rọ̀, ẹ ṣe déédé, ìbáà jẹ́ ìbátan. Kí ẹ sì pé àdéhùn Allāhu. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí

[153] Àti pé dájúdájú èyí ni ọ̀nà Mi (tí ó jẹ́ ọ̀nà) tààrà. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú ọ̀nà (mìíràn) nítorí kí ó má baà mu yín yapa ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fun yín nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Rẹ̀)

[154] Lẹ́yìn náà, A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà ní pípé pérépéré fún ẹni tí ó máa ṣe dáadáa. (Ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan. (Ó tún jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn

[155] Èyí ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu) nítorí kí A lè kẹ yín

[156] Nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: “Ọ̀wọ́ ìjọ méjì tí ó ṣíwájú wa ni Wọ́n sọ Tírà kalẹ̀ fún. A sì jẹ́ aláìnímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ wọn.”

[157] Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Dájúdájú Wọn ìbá sọ Tírà kalẹ̀ fún wa ni, àwa ìbá mọ̀nà jù wọ́n lọ.” Ẹ̀rí t’ó yanjú, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí ju ẹni t’ó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, t’ó tún gbúnrí kúrò níbẹ̀? A máa san àwọn t’ó ń gbúnrí kúrò níbi àwọn āyah Wa ní (ẹ̀san) ìyà burúkú nítorí pé wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbẹ̀)

[158] Ṣé wọ́n ń retí n̄ǹkan (mìíràn) bí kò ṣe pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí Olúwa rẹ wá bá wọn tàbí kí apá kan àwọn àmì Olúwa rẹ wá bá wọn? Ní ọjọ́ tí apá kan àwọn àmì Olúwa rẹ bá wá bá wọn, ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà). Sọ pé: “Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí (Ọjọ́ náà)

[159] Dájúdájú àwọn t’ó ya ẹ̀sìn wọn sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ, ìwọ kò ní n̄ǹkan kan ṣe pọ̀ pẹ̀lú wọn. Ọ̀rọ̀ wọn sì ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[160] Ẹnikẹ́ni t’ó bá mú iṣẹ́ dáadáa wá, (ẹ̀san) mẹ́wàá irú rẹ̀ l’ó máa wà fún un. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì mú iṣẹ́ aburú wa, A ò níí san án ní ẹ̀san àyàfi irú rẹ̀. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[161] Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi ti fi ọ̀nà tààrà (’Islām) mọ̀ mí, ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

[162] Sọ pé: "Dájúdájú ìrun mi, ẹran (pípa) mi, ìṣẹ̀mí ayé mi àti ikú mi ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[163] Kò sí akẹgbẹ́ fún Un. Ìyẹn ni Wọ́n pa láṣẹ fún mi. Èmi sì ni ẹni-àkọ́kọ́ àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi)

[164] Sọ pé: "Ṣé èmi yóò tún wá olúwa kan yàtọ̀ sí Allāhu ni, nígbà tí ó jẹ́ pé Òun ni Olúwa gbogbo n̄ǹkan. Ẹ̀mí kan kò sì níí ṣe iṣẹ́ kan àfi fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.”

[165] Òun ni Ẹni tí Ó ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀. Ó sì fi àwọn ipò gbe yín ga ju ara yín lọ nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fun yín. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

Àwọn ibi gíga

Surah 7

[1] ’Alif lām mīm sọ̄d

[2] Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (nìyí). Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí iyèméjì wà nínú ọkàn rẹ nípa rẹ̀ láti fi ṣe ìkìlọ̀ àti ìrántí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[3] Ẹ tẹ̀lé ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn wòlíì (èṣù) lẹ́yìn Rẹ̀. Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí

[4] Mélòó mélòó nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́! Ìyà Wa dé bá wọn ní òru tàbí nígbà tí wọ́n ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́

[5] Igbe ẹnu wọn kò jẹ́ kiní kan nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn ju pé wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí

[6] Nítorí náà, dájúdájú A óò bi àwọn tí A ránṣẹ́ sí léèrè (nípa ìjẹ́pè). Dájúdájú A ó sì bi àwọn Òjíṣẹ́ léèrè (nípa ìjíṣẹ́)

[7] Dájúdájú A óò ròyìn (iṣẹ́ ọwọ́ wọn) fún wọn pẹ̀lú ìmọ̀. Àwa kò ṣàì wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀)

[8] Òdodo ni òṣùwọ̀n Ọjọ́ yẹn. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí àwọn òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè

[9] Ẹnikẹ́ni tí àwọn òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣ’ẹ̀mí ara wọn lófò nítorí pé wọ́n ń ṣàbòsí sí àwọn āyah Wa

[10] Dájúdájú A fun yín ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. A sì ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu fún yín lórí rẹ̀. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá

[11] Dájúdájú A da yín, lẹ́yìn náà A ya àwòrán yín, lẹ́yìn náà A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam." Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, tí kò sí nínú àwọn olùforíkanlẹ̀

[12] (Allāhu) sọ pé: "Kí ni ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí i nígbà tí Mo pa á láṣẹ fún ọ." (Èṣù) wí pé: "Èmi lóore jùlọ sí òun; iná ni O fi dá èmi, O sì dá òun láti ara erùpẹ̀ amọ̀

[13] (Allāhu) sọ pé: "Sọ̀kalẹ̀ kúrò níbí nítorí pé kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ láti ṣègbéraga níbí. Nítorí náà, jáde dájúdájú ìwọ ń bẹ nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ

[14] (Èṣù) wí pé: "Lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé àwọn ènìyàn dìde

[15] (Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ ń bẹ nínú àwọn tí A óò lọ́ lára

[16] (Èṣù) wí pé: "Fún wí pé O ti fi mí sínú anù, èmi yóò jókòó dè wọ́n ní ọ̀nà tààrà Rẹ

[17] Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi yóò wá bá wọn láti iwájú wọn, láti ẹ̀yìn wọn, láti ọ̀tún wọn àti òsì wọn. Ìwọ kò sì níí rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ní olùdúpẹ́ (fún Ọ)

[18] (Allāhu) sọ pé: "Jáde kúrò níbí (kí o sì di) alábùkù, ẹni-àlédànù. Dájúdájú ẹnikẹ́ni t’ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn, dájúdájú Èmi yóò fi gbogbo yín kún inú iná Jahanamọ

[19] Ādam, kí ìwọ àti ìyàwó rẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Nítorí náà, ẹ máa jẹ níbikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí nítorí kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí

[20] Èṣù sì kó ròyíròyí bá àwọn méjèèjì nítorí kí ó lè fi ohun tí A fi pamọ́ nínú ìhòhò ara wọn hàn wọ́n. Ó sì wí pé: "Olúwa ẹ̀yin méjèèjì kò kọ igi yìí fun yín bí kò ṣe pé kí ẹ̀yin méjèèjì má baà di mọlāika tàbí kí ẹ̀yin méjèèjì má baà di olùṣegbére

[21] Ó sì búra fún àwọn méjèèjì pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn fún ẹ̀yin méjèèjì

[22] Ó sì tan àwọn méjèèjì jẹ. Nígbà tí àwọn méjèèjì tọ́ igi náà wò, ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bora wọn. Olúwa àwọn méjèèjì sì pè wọ́n pé: "Ǹjẹ́ Èmi kò ti kọ igi náà fun ẹ̀yin méjèèjì? (Ṣé) Èmi kò sì ti sọ fún ẹ̀yin méjèèjì pé ọ̀tá pọ́nńbélé ni Èṣù jẹ́ fun yín

[23] Àwọn méjèèjì sọ pé: "Olúwa wa, a ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí wa. Tí O ò bá foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa, dájúdájú a máa wà nínú àwọn ẹni òfò." gẹ́gẹ́ bí wọ́n tún ṣe gbàgbọ́ pé ẹ̀jẹ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lórí igi àgbélébùú ti pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn rẹ́ fún gbogbo àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí igi àgbélébùú. Allāhu sì sọ pé ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmìíràn mọ́ tirẹ̀. Ìkẹrin; àwọn kristiẹni di olùṣìnà nípa bí wọ́n ṣe sọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun tí wọ́n ń jọ́sìn fún nítorí pé wọ́n gbà pé ìkíní kejì wọn nìkan ni kò ní ègún ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ lọ́rùn àti pé wọ́n tún gbàgbọ́ pé Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) jẹ èso igi náà. Jíjẹ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn àwọn méjèèjì nìkan kò sí ẹ̀ṣẹ̀ èso jíjẹ lọ́rùn àwọn ọmọ wọn kan kan. Kókó kejì: àwọn méjèèjì tọrọ àforíjìn lórí àṣìṣe náà tí wọ́n sì sọ gbogbo ọmọ rẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀ èso nípasẹ̀ rẹ̀ òhun ni pé

[24] (Allāhu) sọ pé: "Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fun yín ní orí ilẹ̀ fún ìgbà (díẹ̀).”

[25] (Allāhu) sọ pé: “Lórí ilẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣẹ̀mí, lórí rẹ̀ ni ẹ̀yin yóò máa kú sí, A ó sì mu yín jáde láti inú rẹ̀.”

[26] Ọmọ (Ànábì) Ādam, dájúdájú A ti sọ aṣọ kalẹ̀ fun yín, tí ó máa bo ìhòhò yín àti ohun àmúṣọrọ̀. Aṣọ ìbẹ̀rù Allāhu, ìyẹn l’ó sì lóore jùlọ. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[27] Ọmọ (Ànábì) Ādam, ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù kó ìfòòró ba yín gẹ́gẹ́ bí ó ṣe yọ àwọn òbí yín méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó gba aṣọ kúrò lára àwọn méjèèjì nítorí kí ó lè fi ìhòhò wọn hàn wọ́n. Dájúdájú ó ń ri yín; òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ (ń ri yín) ní àyè tí ẹ̀yin kò ti rí wọn. Dájúdájú Àwa fi Èṣù ṣe ọ̀rẹ́ fún àwọn tí kò gbàgbọ́

[28] Nígbà tí wọ́n bá sì ṣe ìbàjẹ́ kan, wọ́n á wí pé: "A bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ ni. Allāhu l’Ó sì pa á láṣẹ fún wa." Sọ pé: "Dájúdájú Allāhu kì í p’àṣẹ ìbàjẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni

[29] Sọ pé: “Olúwa mi p’àṣẹ ṣíṣe déédé. Kí ẹ sì dojú yín kọ (Allāhu) ní gbogbo mọ́sálásí. Ẹ pè É (kí ẹ jẹ́) olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un. Gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe da yín (tí ẹ fi di alààyè), ẹ máa padà (di alààyè lẹ́yìn ikú yín).”

[30] Apá kan ni Ó fi mọ̀nà, apa kan sì ni ìṣìnà kò lé lórí. (Nítorí pé) dájúdájú wọ́n mú àwọn èṣù ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà

[31] Ọmọ (Ànábì) Ādam, ẹ wọ (aṣọ) ọ̀ṣọ́ yín nígbàkígbà tí ẹ bá ń lọ sí mọ́sálásí. Ẹ jẹ, ẹ mu, kí ẹ sì má yàpà. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn àpà

[32] Sọ pé: “Ta l’ó ṣe ọ̀ṣọ́ Allāhu, tí Ó mú jáde fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan dáadáa nínú arísìkí ní èèwọ̀?” Sọ pé: “Ó wà fún àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo nínú ìṣẹ̀mí ayé. Tiwọn nìkan sì ni l’Ọ́jọ́ Àjíǹde." Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó nímọ̀.”

[33] Sọ pé: "Ohun tí Olúwa mi ṣe ní èèwọ̀ ni àwọn ìwà ìbàjẹ́ – èyí t’ó fojú hàn nínú rẹ̀ àti èyí t’ó pamọ́ –, ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ọ̀tẹ̀ ṣíṣe láì lẹ́tọ̀ọ́, bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ – èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún – àti ṣíṣe àfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu

[34] Àkókò kan ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan; nígbà tí àkókò wọn bá sì dé, wọn kó lè sún un síwájú di àkókò kan, wọn kò sì lè fà á sẹ́yìn

[35] Ọmọ (Ànábì) Ādam, nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ nínú yín bá wá ba yín, tí wọn yóò máa ka àwọn āyah Mi fun yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Mi), tí ó sì ṣàtúnṣe, kò níí sí ìbẹ̀rù kan fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́

[36] Àwọn t’ó bá sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, tí wọ́n sì ṣègbéraga sí i, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[37] Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí t’ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Ìpín àwọn wọ̀nyẹn nínú kádàrá yóò máa tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa yóò wá bá wọn, tí wọn yóò gba ẹ̀mí wọn. Wọn yó sì sọ pé: "Níbo ni àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀yin ń pè lẹ́yìn Allāhu wà?" Wọn yóò wí pé: “Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́." Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́.”

[38] (Allāhu) sọ pé: "Ẹ wọlé ti àwọn ìjọ t’ó ti ré kọjá lọ ṣíwájú yín nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn (tí wọ́n ti wà) nínú Iná." Ìgbàkígbà tí ìjọ kan bá wọ (inú Iná), wọn yóò máa ṣẹ́bi fún àwọn ìjọ rẹ̀ (t’ó ti wà níbẹ̀ ṣíwájú wọn), títí di ìgbà tí gbogbo wọn yóò fi pàdé ara wọn nínú Iná. (Ìgbà yìí ni) àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn yóò wí fún àwọn ẹni ìṣáájú wọn pé: "Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ṣì wá lọ́nà. Nítorí náà, fún wọn ni ìlọ́po ìyà méjì nínú Iná." (Allāhu) sọ pé: "Ìkọ̀ọ̀kan (yín) l’ó ní ìlọ́po ìyà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀

[39] Àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn yó sí wí fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn pé: "Kò sí àjùlọ kan fun yín lórí wa. Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[40] Dájúdájú àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, tí wọ́n sì ṣègbéraga sí i, Wọn kò níí ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ fún wọn. Wọn kò sì níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra títí ràkúnmí yóò wọ inú ihò abẹ́rẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san

[41] Ìtẹ́ wà fún wọn nínú iná Jahanamọ. Òrùlé sì wà fún wọn ní òkè wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san

[42] Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ lódodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere - A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀ - àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[43] A ó sì mú inúnibíni kúrò nínú ọkàn wọn. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn yóò sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fi wá mọ̀nà yìí. Àwa ìbá tí mọ̀nà, tí kì í bá ṣe pé Allāhu tọ́ wa sí ọ̀nà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá.” Wọ́n sì máa pè wọ́n pé: “Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fun yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

[44] Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò pe àwọn èrò inú Iná pé: "A ti rí ohun tí Olúwa wa ṣe àdéhùn rẹ̀ fún wa ní òdodo. Ǹjẹ́ ẹ̀yin náà rí ohun tí Olúwa yín ṣe àdéhùn (rẹ̀ fun yín) ní òdodo?" Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Olùpèpè kan yó sì pèpè láààrin wọn pé: "Kí ibi dandan Allāhu máa bẹ lórí àwọn alábòsí

[45] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì tún ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[46] Gàgá yóò wà láààrin èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná. Àwọn ènìyàn kan máa wà lórí ògiri (gàgá náà), wọn yó sì dá ẹnì kọ̀ọ̀kan (ìjọ méjèèjì) mọ̀ pẹ̀lú àmì wọn. Wọn yóò pe àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: “Kí àlàáfíà máa bẹ fun yín.” Wọn kò ì wọ (inú) rẹ̀, wọ́n sì ti ń jẹ̀rankàn (rẹ̀)

[47] Nígbà tí wọ́n bá yíjú wọn sí ọ̀gangan àwọn èrò inú Iná, wọn yóò sọ pé: “Olúwa wa, má fi wá sọ́dọ̀ àwọn ìjọ alábòsí.”

[48] Àwọn èrò orí ògiri (gàgá náà), yóò pe àwọn ènìyàn kan tí wọ́n mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn, wọn yó sì sọ pé: “Ohun tí ẹ kójọ nílé ayé àti ṣíṣe ìgbéraga yín sí ìgbàgbọ́ òdodo kò rọ̀ yín lọ́rọ̀ mọ́ (báyìí)”

[49] (Allāhu) yóò sọ fún èrò inú Iná pé: “Ṣé àwọn (èrò orí ògiri) wọ̀nyí ni ẹ̀yin ń búra pé Allāhu kò níí ṣíjú àánú wò? (Nítorí náà, ẹ̀yin èrò orí ògiri) ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò níí sí ìbẹ̀rù kan fun yín. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́.”

[50] Èrò inú Iná yóò pe èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra pé: “Ẹ fún wa nínú omi tàbí nínú ohun tí Allāhu pa lésè fun yín.” Wọn yóò sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ti ṣe méjèèjì ní èèwọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

[51] Àwọn t’ó sọ ẹ̀sìn wọn di ìranù àti eré ṣíṣe, ìṣẹ̀mí ayé sì kó ẹ̀tàn bá wọn, ní òní ni A óò gbàgbé wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ wọn ti òní yìí àti (bí) wọ́n ṣe ń tako àwọn āyah Wa

[52] A kúkú ti mú tírà kan wá bá wọn, tí A ṣàlàyé rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀. (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo

[53] Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀? Lọ́jọ́ tí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ bá dé, àwọn t’ó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́

[54] Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá. Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[55] Ẹ pe Olúwa yín pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ohùn jẹ́ẹ́jẹ́. Dájúdájú (Allāhu) kò fẹ́ràn àwọn alákọyọ

[56] Ẹ má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ẹ pe Allāhu pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìrètí. Dájúdájú àánú Allāhu súnmọ́ àwọn olùṣe-rere

[57] Òun ni Ẹni t’Ó ń rán atẹ́gùn (t’ó jẹ́) ìró ìdùnnú ṣíwájú àánú Rẹ̀, títí (atẹ́gùn náà) yóò fi gbé ẹ̀ṣújò t’ó wúwo, tí A sì máa wọ́ ọ lọ sí òkú ilẹ̀. Nígbà náà, A máa fi sọ omi kalẹ̀. A sì máa mú oríṣiríṣi èso jáde. Báyẹn ni A ó ṣe mú àwọn òkú jáde nítorí kí ẹ lè lo ìrántí

[58] (Ilẹ̀) ìlú t’ó dára, àwọn irúgbìn rẹ̀ yóò jáde pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Èyí tí kò sì dára, (irúgbìn rẹ̀) kò níí jáde àfi (díẹ̀) pẹ̀lú ìnira. Báyẹn ni A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà fún ìjọ t’ó ń dúpẹ́

[59] Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú mò ń bẹ̀rù ìyà Ọjọ́ Ńlá fun yín

[60] Àwọn àgbààgbà nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: "Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[61] Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, kò sí ìṣìnà kan lọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[62] Mò ń jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mò ń fun yín ní ìmọ̀ràn rere. Àti pé ohun tí ẹ ò mọ̀ ni èmi mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu

[63] Àti pé ṣé ẹ ṣèèmọ̀ pé ìrántí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín dé ba yín ni, (èyí tí Wọ́n fún) ọkùnrin kan nínú yín nítorí kí ó lè kìlọ̀ fun yín; nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí A lè kẹ yín

[64] Wọ́n sì pè é lópùrọ́. Nítorí náà, A gba òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ là nínú ọkọ̀ ojú-omi. A sì tẹ àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ rì. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ t’ó fọ́jú (sí òdodo)

[65] A tún rán (ẹnì kan) sí àwọn ará ‘Ād, arákùnrin wọn, Hūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni

[66] Àwọn àgbààgbà t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú agọ̀. Àti pé dájúdájú à ń rò pé o wà nínú àwọn òpùrọ́.”

[67] Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, kò sí agọ̀ kan lára mi, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[68] Mò ń jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Èmi sì ni onímọ̀ràn rere, olùfọkàntán fun yín

[69] Àti pé ṣé ẹ ṣèèmọ̀ pé ìrántí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín dé ba yín ni, (èyí tí Wọ́n fún) ọkùnrin kan nínú yín, nítorí kí ó lè kìlọ̀ fun yín? Ẹ rántí nígbà tí (Allāhu) fi yín ṣe àrólé lẹ́yìn ìjọ (Ànábì) Nūh. Ó tún ṣe àlékún agbára fun yín nínú ìṣẹ̀dá (yín). Nítorí náà, ẹ rántí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu, nítorí kí ẹ lè jèrè

[70] Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí á lè jọ́sìn fún Allāhu nìkan ṣoṣo àti nítorí kí á lè pa ohun tí àwọn bàbá ńlá wa ń jọ́sìn fún tì? Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

[71] Ó sọ pé: “Ìyà àti ìbínú kúkú ti sọ̀kalẹ̀ sórí yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ṣé ẹ óò máa jà mí níyàn nípa àwọn orúkọ (òrìṣà) kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fún lórúkọ - Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un? – Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”

[72] Nítorí náà, pẹ̀lú àánú láti ọ̀dọ̀ Wa, A gba òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ là. A sì pa àwọn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́ run; wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo

[73] A tún rán (ẹnì kan) sí àwọn ìran Thamūd, arákùnrin wọn, Sọ̄lih. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Iṣẹ́ ìyanu kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín; èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. (Ó jẹ́) àmì kan fun yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ọwọ́ aburú kàn án nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baà jẹ yín

[74] Ẹ tún rántí nígbà tí (Allāhu) ṣe yín ní àrólé lẹ́yìn àwọn ara ‘Ād. Ó sì fun yín ní ilé ìgbé lórí ilẹ̀; ẹ̀ ń kọ́ ilé ńláńlá sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àpáta. Ẹ rántí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu, kí ẹ sì má ṣe rìn lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́

[75] Àwọn àgbààgbà t’ó ṣègbéraga nínú ìjọ rẹ̀ wí fún àwọn tí wọ́n fojú tínrín, (ìyẹn) àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo nínú wọn, pé: "Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé dájúdájú Sọ̄lih ni Òjíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?" Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú àwa gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi rán an níṣẹ́.”

[76] Àwọn t’ó ṣègbéraga wí pé: “Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ẹ̀yin gbàgbọ́.”

[77] Nítorí náà, wọ́n gún abo ràkúnmí náà pa. Wọ́n sì tàpá sí àṣẹ Olúwa wọn. Wọ́n sì wí pé: “Sọ̄lih, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa ṣẹ tí o bá wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.”

[78] Nítorí náà, ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn

[79] Nígbà náà, (Sọ̄lih) ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, mo kúkú ti jẹ́ iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mo sì ti fun yín ní ìmọ̀ràn rere ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ràn àwọn onímọ̀ràn rere.”

[80] (Rántí Ànábì) Lūt, nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ óò máa ṣe ìbàjẹ́ ni tí kò sí ẹnì kan nínú àwọn ẹ̀dá t’ó ṣe irú rẹ̀ rí

[81] Dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) ń lọ jẹ adùn (ìbálòpọ̀) lára àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín) dípò àwọn obìnrin! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni yín

[82] Kí sì ni ó jẹ́ èsì ìjọ rẹ̀ bí kò ṣe pé, wọ́n wí pé: “Ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ìlú yín, dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn kan t’ó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).”

[83] Nígbà náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀ tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun

[84] A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Wo bí ìkángun àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe rí

[85] (A tún rán ẹnì kan) sí àwọn ará Mọdyan, arákùnrin wọn, Ṣu‘aeb. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Ẹ sì má ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ lẹ́yìn àtúnṣe rẹ̀. Ìyẹn sì lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[86] Ẹ má ṣe lúgọ sí gbogbo ọ̀nà láti máa dẹ́rùba àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń ṣẹ́rí ẹni t’ó gbagbọ́ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ẹ sì ń fẹ́ k’ó wọ́. Ẹ rántí o, nígbà tí ẹ kéré (lóǹkà), Allāhu sọ yín di púpọ̀. Ẹ sì wo bí ìkángun àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ṣe rí

[87] Tí ó bá jẹ́ pé igun kan nínú yín gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́, tí igun kan kò sì gbàgbọ́, nígbà náà ẹ ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ láààrin wa. Òun sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́

[88] Àwọn àgbààgbà t’ó ṣègbéraga nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú a máa lé ìwọ Ṣu‘aeb àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ jáde kúrò nínú ìlú wa tàbí ẹ gbọ́dọ̀ padà sínú ẹ̀sìn wa.” (Ṣu‘aeb) sọ pé: "Ṣé (ẹ máa dá wa padà sínú ìbọ̀rìṣà) t’ó sì jẹ́ pé ẹ̀mí wa kọ̀ ọ́

[89] Dájúdájú a ti dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tí a bá fi lè padà sínú ẹ̀sìn yín lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti yọ wá kúrò nínú rẹ̀. Àti pé kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti padà sínú rẹ̀ àfi tí Allāhu, Olúwa wa bá fẹ́. Olúwa wa gbòòrò tayọ gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú ìmọ̀. Allāhu l’a gbáralé. Olúwa wa, ṣe ìdájọ́ láààrin àwa àti ìjọ wa pẹ̀lú òdodo, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́

[90] Àwọn àgbààgbà t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ wí pé: “Dájúdájú tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé Ṣu‘aeb, nígbà náà ẹ̀yin ti di ẹni òfò nìyẹn.”

[91] Nítorí náà, ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn

[92] Àwọn t’ó pe Ṣu‘aeb lópùrọ́ sì dà bí ẹni tí kò gbé nínú ìlú wọn rí; àwọn t’ó pe Ṣu‘aeb lópùrọ́ ni wọ́n jẹ́ ẹni òfò

[93] Nítorí náà, (Ṣu‘aeb) ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, mo kúkú ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa mi fun yín. Mo sì ti fun yín ní ìmọ̀ràn rere. Báwo ni èmi yóò ṣe tún máa banújẹ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”

[94] A ò rán Ànábì kan sí ìlú kan láì jẹ́ pé A fi ìpọ́njú àti ìnira kan àwọn ará ìlú náà nítorí kí wọ́n lè rawọ́-rasẹ̀ (sí Allāhu)

[95] Lẹ́yìn náà, A fi (ohun) rere rọ́pò aburú (fún wọn) títí wọ́n fi pọ̀ (lóǹkà àti lọ́rọ̀). Wọ́n sì wí pé: “Ọwọ́ ìnira àti ìdẹ̀ra kúkú ti kan àwọn bàbá wa rí.” Nítorí náà, A gbá wọn mú lójijì, wọn kò sì fura

[96] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú àwọn ará ìlú náà gbàgbọ́ lódodo ni, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), A ìbá ṣínà àwọn ìbùkún fún wọn láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n pe òdodo nírọ́. Nígbà náà, A mú wọn nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[97] Ṣé àwọn ará ìlú náà fàyà balẹ̀ pé ìyà Wa (kò lè) dé bá wọn ní alẹ́ ni, nígbà tí wọ́n bá ń sùn lọ́wọ́

[98] Ṣé àwọn ará ìlú náà fàyà balẹ̀ pé ìyà Wa (kò lè) dé bá wọn ní ìyálẹ̀ta ni, nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré lọ́wọ́

[99] Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ sí ète Allāhu ni? Kò mà sí ẹni t’ó máa fàyà balẹ̀ sí ète Allāhu àfi ìjọ olófò

[100] Ṣé kò hàn sí àwọn t’ó jogún ilẹ̀ lẹ́yìn àwọn onílẹ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ ni), Àwa ìbá fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn mú wọn, Àwa ìbá sì fi èdídí bo ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́rọ̀ (mọ́)

[101] Àwọn ìlú wọ̀nyí ni À ń fún ọ ní ìró nínú ìròyìn wọn. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yánjú wá bá wọn. (Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ náà,) wọn kò kúkú níí gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ t’ó ṣíwájú wọn) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn). Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́

[102] Àwa kò rí pípé àdéhùn ní ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn. Àti pé ńṣe ni A rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ní òbìlẹ̀jẹ́

[103] Lẹ́yìn náà, A gbé (Ànábì) Mūsā dìde lẹ́yìn wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àbòsí sí àwọn àmì náà. Nítorí náà, wo bí ìkángun àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ṣe rí

[104] (Ànábì) Mūsā sọ pé: "Fir‘aon, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[105] Dandan ni fún mi pé èmi kò níí ṣàfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo. Mo sì kúkú ti mú ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá mi lọ

[106] (Fir‘aon) wí pé: “Tí o bá jẹ́ ẹni t’ó mú àmì kan wá, mú un jáde tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”

[107] Nígbà náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé

[108] Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ, ó sì di funfun (gbòlà) fún àwọn olùwòran

[109] Àwọn ìjòyè nínú ìjọ Fir‘aon wí pé: "Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa

[110] Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni." (Fir‘aon wí pé: ) “Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”

[111] Wọ́n sì wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú

[112] (pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ

[113] Àwọn òpìdán sì dé wá bá Fir‘aon. Wọ́n wí pé: “Dájúdájú ẹ̀san gbọ́dọ̀ wà fún wa tí àwa bá jẹ́ olùborí.”

[114] Ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Àti pé dájúdájú ẹ̀yin gbọ́dọ̀ wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”

[115] (Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, o máa (kọ́kọ́) ju ọ̀pá sílẹ̀ ni, tàbí àwa ni a máa (kọ́kọ́) jù ú sílẹ̀.”

[116] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, wọ́n fi pidán lójú àwọn ènìyàn. Wọ́n sì ṣẹ̀rùbà wọ́n. Wọ́n wá pẹ̀lú idán ńlá

[117] A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” Nígbà náà, ó sì ń gbé ohun tí wọ́n ti pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló

[118] Nítorí náà, òdodo dé. Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì bàjẹ́

[119] Nítorí náà, A borí wọn níbẹ̀ yẹn. Wọ́n sì darí wálé ní ẹni yẹpẹrẹ

[120] Iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wólẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu)

[121] Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[122] Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn

[123] Fir‘aon wí pé: “Ẹ ti gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín! Dájúdájú èyí ni ète kan tí ẹ ti hun nínú ìlú nítorí kí ẹ lè kó àwọn ará ìlú jáde kúrò nínú rẹ̀. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀

[124] Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”

[125] Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa sì ni a máa fàbọ̀ sí

[126] Àti pé o ò tako kiní kan lára wa láti fìyà jẹ wá bí kò ṣe nítorí pé a gba àwọn àmì Olúwa wa gbọ́ nígbà tí ó dé bá wa. Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu. Kí O sì pa wá sípò mùsùlùmí

[127] Àwọn ìjòyè nínú ìjọ Fir‘aon wí pé: "Ṣé ìwọ yóò fi Mūsā àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti nítorí kí ó lè pa ìwọ àti àwọn òrìṣà rẹ tì?" (Fir‘aon) wí pé: "A óò máa pa àwọn ọmọkùnrin wọn ni. A ó sì máa dá àwọn ọmọbìnrin wọn sí. Dájúdájú àwa ni alágbára lórí wọn

[128] (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ fi Allāhu wá ìrànlọ́wọ́, kí ẹ sì ṣe sùúrù. Dájúdájú ti Allāhu ni ilẹ̀. Ó sì ń jogún rẹ̀ fún ẹni t’Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ìgbẹ̀yìn (rere) sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[129] Wọ́n sọ pé: “Wọ́n ni wá láraṣíwájú kí o tó wá bá wa àti lẹ́yìn tí o dé bá wa.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò pa àwọn ọ̀tá yín run. Ó sì máa fi yín rọ́pò (wọn) lórí ilẹ̀. Nígbà náà, (Allāhu) yó sì wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe.”

[130] Dájúdájú A gbá ènìyàn Fir‘aon mú pẹ̀lú ọ̀dá òjò àti àdínkù t’ó bá àwọn èso nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[131] Nígbà tí ohun rere bá dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Tiwa ni èyí.” Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á ṣàfitì aburú náà sọ́dọ̀ (Ànábì) Mūsā àti ẹni t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Kíyè sí i, àmì aburú wọn kúkú wà (nínú kádàrá wọn) lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀

[132] Wọ́n sì wí pé: “Ohunkóhun tí o bá mú wá fún wa ní àmì láti fi pidán fún wa, àwa kò níí gbà ọ́ gbọ́.”

[133] Nítorí náà, A sì fi ẹ̀kún omi, àwọn eṣú, àwọn kòkòrò iná, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ àti ẹ̀jẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn ní àwọn àmì tí ń tẹ̀léra wọn, t’ó fojú hàn. Ńṣe ni wọ́n tún ṣègbéraga; wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀

[134] Nígbà tí ìyà sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí, wọ́n wí pé: “Mūsā, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe fún ọ. Dájúdájú tí o bá fi lè gbé ìyà náà kúrò fún wa (pẹ̀lú àdúà rẹ), dájúdájú a máa gbà ọ́ gbọ́, dájúdájú a sì máa jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá ọ lọ.”

[135] Nígbà tí A gbé ìyà náà kúrò fún wọn fún àkókò kan tí wọn yóò lò (nínú ìṣẹ̀mí wọn), nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn

[136] Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn, A sì tẹ̀ wọ́n rì sínú agbami odò nítorí pé wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀

[137] A sì jogún àwọn ibùyọ òòrùn lórí ilẹ̀ ayé àti ibùwọ̀ òòrùn rẹ̀, tí A fi ìbùnkún sí, fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fojú tínrín. Ọ̀rọ̀ Olúwa Rẹ, t’ó dára sì kò lé àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lórí nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù. A sì pa ohun tí Fir‘aon àti ìjọ rẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n ń kọ́ nílé run

[138] A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄‘īl la agbami odò já. Nígbà náà, wọ́n kọjá lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n dúró ti àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì wí pé: “Mūsā, ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan.” (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni ìjọ aláìmọ̀kan

[139] Dájúdájú àwọn wọ̀nyí máa parun lórí ohun tí wọ́n ń ṣe (yìí). Irọ́ sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.”

[140] (Ànábì) Mūsā sọ pé: "Ṣé kí èmi tún ba yín wá ọlọ́hun kan tí ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni? Òun l’Ó sì ṣe àjùlọ oore fun yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín)

[141] (Ẹ rántí) nígbà tí A là yín lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, wọ́n ń pa àwọn ọmọkùnrin yín tààrà, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín

[142] Àti pé A yan ọgbọ̀n òru fún (Ànábì) Mūsā. A tún fi mẹ́wàá kún un. Nítorí náà, àkókò (tí) Olúwa Rẹ̀ (yóò fi bá a sọ̀rọ̀ sì máa) parí ní òru ogójì. (Ànábì) Mūsā sọ fún arákùnrin rẹ̀, Hārūn, pé: “Rólé dè mí láààrin àwọn ènìyàn mi. Kí o máa ṣe àtúnṣe. Má sì ṣe tẹ̀lé ọ̀nà àwọn òbìlẹ̀jẹ́.”

[143] Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé ní àkókò tí A fún un, Olúwa rẹ̀ sì bá a sọ̀rọ̀. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, fi ara Rẹ hàn mí, kí èmi lè rí Ọ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìwọ kò lè rí Mi. Ṣùgbọ́n wo àpáta (yìí), tí ó bá dúró ṣinṣin sí àyè rẹ̀, láìpẹ́ o máa rí Mi.” Nígbà tí Olúwa rẹ̀ sì (rọra) fi ara Rẹ̀ han àpáta, Ó sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. (Ànábì) Mūsā sì ṣubú lulẹ̀, ó dákú. Nígbà tí ó tají, ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, èmi ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Èmi sì ni àkọ́kọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ní àsìkò tèmi)

[144] (Allāhu) sọ pé: "Mūsā, dájúdájú Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn ènìyàn pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Mi àti ọ̀rọ̀ Mi. Nítorí náà, gbá ohun tí Mo fún ọ mú. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́

[145] A sì kọ gbogbo n̄ǹkan fún un sínú àwọn wàláà. (Ó jẹ́) wáàsí àti àlàyé ọ̀rọ̀ fún gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣàmúlò rẹ̀ dáradára. Kí o sì pa ìjọ rẹ láṣẹ pé kí wọ́n ṣàmúlò n̄ǹkan dáadáa t’ó ń bẹ nínú rẹ̀. Èmi yóò fi ilé àwọn arúfin hàn yín

[146] Èmi yóò ṣẹ́rí àwọn t’ó ń ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ kúrò níbi àwọn àmì Mi. Tí wọ́n bá sì rí gbogbo àmì, wọn kò níí gbà á gbọ́. Tí wọ́n bá rí ọ̀nà ìmọ̀nà, wọn kò níí mú un ní ọ̀nà. Tí wọ́n bá sì rí ọ̀nà ìṣìnà, wọn yóò mú un ní ọ̀nà. Ìyẹn nítorí pé wọ́n pe àwọn àmì Wa nírọ́; wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀

[147] Àwọn t’ó sì pe àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ní irọ́, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan ni bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[148] Àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā, lẹ́yìn rẹ̀ (nígbà tí ó fi lọ bá Allāhu sọ̀rọ̀), wọ́n mú nínú ọ̀ṣọ́ wọn (láti fi ṣe) ère ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi, ó sì ń dún (bíi màálù). Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú kò lè bá wọn sọ̀rọ̀ ni, kò sì lè fi ọ̀nà mọ̀ wọ́n? Wọ́n sì sọ ọ́ di àkúnlẹ̀bọ. Wọ́n sì jẹ́ alábòsí

[149] Nígbà tí ó di àbámọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ tán, wọ́n sì rí i pé àwọn ti ṣìnà, wọ́n wí pé: “Tí Olúwa wa kò bá ṣàánú wa, kí Ó sì foríjìn wá, dájúdájú àwa yóò wà nínú àwọn ẹni òfò.”

[150] Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sì padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́, ó sọ pé: “Ohun tí ẹ fi rólé dè mí lẹ́yìn mi burú. Ṣé ẹ ti kánjú pa àṣẹ Olúwa yín tì ni?" Ó sì ju àwọn wàláà sílẹ̀, ó gbá orí arákùnrin rẹ̀ mú, ó sì ń wọ́ ọ mọ́ra. (Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi ò, dájúdájú àwọn ènìyàn ni wọ́n fojú tínrín mi, wọ́n sì fẹ́ẹ̀ pa mí. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ̀ mí. Má sì ṣe mú mi mọ́ ìjọ alábòsí.”

[151] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, foríjin èmi àti arákùnrin mi. Kí O sì fi wá sínú ìkẹ́ Rẹ. Ìwọ sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

[152] Dájúdájú àwọn t’ó sọ (ère) ọmọ màálù di àkúnlẹ̀bọ, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àti ìyẹpẹrẹ yóò bá wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn aládapa irọ́ ní ẹ̀san

[153] Àwọn t’ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ aburú, lẹ́yìn náà tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú lẹ́yìn èyí Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[154] Nígbà tí ìbínú (Ànábì) Mūsā sì wálẹ̀, ó mú àwọn wàláà náà. Ìmọ̀nà àti àánú ń bẹ nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù Olúwa wọn

[155] (Ànábì) Mūsā sì yan àádọ́rin ọkùnrin nínú ìjọ rẹ̀ fún àkókò tí A fún un (láti wá tọrọ àforíjìn fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ibi àpáta Sīnā’), ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì sì gbá wọn mú, ó sọ pé: “Olúwa mi, tí O bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, Ìwọ ìbá ti pa àwọn àti èmi rẹ́ ṣíwájú (kí á tó wá síbí); ṣé Ìwọ yóò pa wá rẹ́ nítorí ohun tí àwọn òmùgọ̀ nínú wa ṣe ni? Kí ni ohun (tí wọ́n ṣe) bí kò ṣe àdánwò Rẹ; Ò ń fi ṣi ẹni tí O bá fẹ́ lọ́nà, O sì ń tọ́ ẹni tí O bá fẹ́ sọ́nà. Ìwọ ni Aláàbò wa. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn aláforíjìn

[156] Kí O sì kọ àkọsílẹ̀ rere fún wa ní ayé yìí àti ní ọ̀run. Dájúdájú àwa ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìyà Mi, Mo ń fi jẹ ẹni tí Mo bá fẹ́. Àti pé ìkẹ́ Mi gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ. Èmi yó sì kọ (ìkẹ́ Mi) mọ́ àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Mi), tí wọ́n sì ń yọ Zakāh àti àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú àwọn āyah Wa.”

[157] Àwọn t’ó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa léèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn t’ó wúwo) àti àjàgà t’ó ń bẹ lọ́rùn wọn kúrò fún wọn; àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n bu iyì fún un, tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè

[158] Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu sí gbogbo yín pátápátá. (Allāhu) Ẹni t’Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ẹ tẹ̀lé e nítorí kí ẹ lè mọ̀nà

[159] Ó wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ìjọ kan t’ó ń fi òdodo tọ́ (àwọn ènìyàn) sọ́nà. Wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ pẹ̀lú rẹ̀

[160] A sì pín wọn sí ìran méjìlá ní ìjọ-ìjọ. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ wá omi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, pé: “Fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ na àpáta.” (Ó ṣe bẹ́ẹ̀) orísun omi méjìlá sì ṣẹ́yọ lára rẹ̀. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ti dá ibùmu wọn mọ̀. A tún fi ẹ̀ṣújò ṣíji bò wọ́n. A sọ (ohun mímu) mọ́nnù àti (ohun jíjẹ) salwā kalẹ̀ fun wọ́n. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fun yín. Wọn kò sì ṣe àbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí

[161] (Ẹ rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí. Ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ níbikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì sọ pé: ‘Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.’ Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùtẹríba. A máa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.”

[162] Àwọn t’ó ṣàbòsí kúkú yí ọ̀rọ̀ náà padà sí òmíràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. A sì sọ ìyà kalẹ̀ láti sánmọ̀ lé wọn lórí nítorí pé wọ́n ń ṣe àbòsí

[163] Bi wọ́n léèrè nípa ìlú t’ó wà ní ẹ̀bádò, nígbà tí wọ́n kọjá ẹnu-àlà nípa ọjọ́ Sabt, nígbà tí ẹja wọn ń wá bá wọn ní ọjọ́ Sabt wọn, wọ́n sì máa léfòó sí ojú odò, ọjọ́ tí kì í bá sì ṣe ọjọ́ Sabt wọn, wọn kò níí wá bá wọn. Báyẹn ni A ṣe ń dán wọn wò nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́

[164] (Rántí) nígbà tí ìjọ kan nínú wọn wí pé: “Nítorí kí ni ẹ fí ń ṣe wáàsí fún ìjọ kan tí Allāhu máa parẹ́ tàbí tí Ó máa jẹ níyà líle?” Wọ́n sọ pé: “(Kí ó lè jẹ́) àwáwí lọ́dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu) ni.”

[165] Nígbà tí wọ́n sì gbàgbé ohun tí wọ́n fi ṣèrántí fún wọn, A gba àwọn t’ó ń kọ aburú là. A sì fi ìyà t’ó le jẹ àwọn t’ó ṣàbòsí nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́

[166] Nígbà tí wọ́n tayọ ẹnu-àlà níbi ohun tí A kọ̀ fún wọn, A sọ fún wọn pé: “Ẹ di ọ̀bọ, ẹni ìgbéjìnnà sí ìkẹ́.”

[167] (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ ọ́ di mímọ̀ pé dájúdájú Òun yóò gbé ẹni tí ó máa fi ìyà burúkú jẹ wọ́n dìde sí wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[168] A pín wọn lórí ilẹ̀ sí ìjọ-ìjọ; àwọn ẹni rere wà nínú wọn, àwọn mìíràn tún wà nínú wọn. A sì fi àwọn ohun rere àti ohun burúkú dán wọn wò kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo)

[169] Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn; wọ́n jogún Tírà (Taorāt àti ’Injīl), wọ́n sì ń gba (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) oore ilé ayé yìí (láti kọ ìkọkúkọ sínú rẹ̀), wọ́n sì ń wí pé: “Wọn yóò foríjìn wá.” Tí (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) oore irú rẹ̀ bá tún wá bá wọn, wọ́n máa gbà á. Ṣé A kò ti bá wọn ṣe àdéhùn nínú Tírà pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo? Wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀! Ilé ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni

[170] Àwọn t’ó ń mú Tírà lò dáradára, tí wọ́n ń kírun, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san àwọn t’ó ń ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ wọn) ráre

[171] (Rántí) nígbà tí A gbé àpáta ga sókè orí wọn, ó sì dà bí ibòji. Wọ́n sì lérò pé ó máa wó lu àwọn mọ́lẹ̀, (A sì sọ fún wọn pé): “Ẹ gbá ohun tí A fun yín mú dáadáa, kí ẹ sì máa rántí ohun t’ó ń bẹ nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).”

[172] (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ādam, Ó fa àrọ́mọdọ́mọ wọn jáde láti (ìbàdí ní) ẹ̀yìn (bàbá ńlá) wọn, Ó sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí lórí ara wọn pé: “Ṣé Èmi kọ́ ni Olúwa yín ni?” Wọ́n sọ pé: “Rárá – (Ìwọ ni Olúwa wa) - a jẹ́rìí sí i.” Nítorí kí ẹ má baà sọ ní Ọjọ́ Àjíǹdé pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa èyí

[173] Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Àwọn bàbá wa ló kúkú bá Allāhu wá akẹgbẹ́ ṣíwájú (wa), àwa sì jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ lẹ́yìn wọn (ni a fi wò wọ́n kọ́ṣe pẹ̀lú àìmọ̀kan). Ṣé Ìwọ yóò pa wá run nítorí ohun tí àwọn t’ó ń tẹ̀lé irọ́ ṣe ni?”

[174] Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Wa, nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo)

[175] Ka ìròyìn ẹni tí A fún ní àwọn āyah Wa fún wọn, tí ó yọra rẹ̀ sílẹ̀ níbi àwọn āyah náà. Nítorí náà, Èṣù tẹ̀lé e lẹ́yìn. Ó sì wà nínú àwọn olùṣìnà

[176] Àti pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fi (ìmọ̀ nípa àwọn āyah Wa) ṣàgbéga fún un. Ṣùgbọ́n ó wayé mọ́yà. Ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀. Nítorí náà, àfiwé rẹ̀ dà bí ajá. Tí o bá lé e síwájú, ó máa yọ ahọ́n síta. Tí o bá sì fi sílẹ̀, ó tún máa yọ ahọ́n síta. Ìyẹn ni àfiwé ìjọ t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Sọ ìtàn náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀

[177] Ìjọ tí ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, wọ́n burú ní àfiwé. Ara wọn sì ni wọ́n ń ṣàbòsí sí

[178] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì ṣì lọ́nà, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò

[179] Dájúdájú A ti dá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àlùjànnú fún iná Jahanamọ (nítorí pé) wọ́n ní ọkàn, wọn kò sì fi gbọ́ àgbọ́yé; wọ́n ní ojú, wọn kò sì fi ríran; wọ́n ní etí, wọn kò sì fi gbọ́ràn. Àwọn wọ̀nyẹn dà bí ẹran-ọ̀sìn. Wọ́n wulẹ̀ sọnù jùlọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni afọ́nú-fọ́ra

[180] Ti Allāhu ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn t’ó ń yẹ̀ kúrò níbi àwọn orúkọ Rẹ̀ tì. A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[181] Ó wà nínú àwọn tí A dá, ìjọ kan t’ó ń fi òdodo tọ́ (àwọn ènìyàn) sọ́nà, wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ pẹ̀lú rẹ̀

[182] Àwọn t’ó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò níí mọ̀

[183] Èmi yóò lọ́ wọn lára. Dájúdájú ète Mi lágbára

[184] Ṣé wọn kò ronú jinlẹ̀ ni? Kò sí wèrè kan kan lára ẹni wọn (ìyẹn, Ànábì s.a.w.). Ta sì ni bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé

[185] Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀? “ọ̀rọ̀ wo nínú ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí ọjọ́ ikú wọn bá dé tàbí lẹ́yìn tí ọjọ́ Àjíǹde bá ṣẹlẹ̀? Bí wọ́n bá padà gba ọ̀rọ̀ al-Ƙu’ān gbọ́ lọ́jọ́ ikú wọn tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde kò lè wúlò fún wọn mọ́ ọ̀rọ̀ irọ́ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí al-Ƙur’ān ti mú ọ̀rọ̀ òdodo wá? Ṣé àwọn ìròrí ìgbà àìmọ́kan àti àwọn àṣà àìmọ́kan èyí tí ìran ẹnì kọ̀ọ̀kan jogún bá láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá ńlá wọn tí wọn kì í ṣe Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun ṣé àwọn ìròrí wọn àti àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà wọn ni wọn yóò máa lò lẹ́yìn al-Ƙur’ān? Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah al-Jāthiyah; 45:6 nítorí pé gbólóhùn t’ó ṣíwájú rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ āyah náà ń sọ̀rọ̀ nípa bí al-Ƙur’ān ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀ òdodo. Èyí wá túmọ̀ sí pé

[186] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un. (Allāhu) yó sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà

[187] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé ìgbà wo ni ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Olúwa mi nìkan ni ìmọ̀ rẹ̀ wà. Kò sí ẹni t’ó lè ṣàfi hàn Àkókò rẹ̀ àfi Òun. Ó ṣòro (láti mọ̀) fún àwọn ará sánmọ̀ àti ará ilẹ̀. Kò níí dé ba yín àfi lójijì.” Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè bí ẹni pé ìwọ nímọ̀ nípa rẹ̀. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Olúwa mi nìkan ni ìmọ̀ rẹ̀ wà, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.”

[188] Sọ pé: “Èmi kò ní agbára àǹfààní tàbí ìnira kan tí mo lè fi kan ara mi àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Tí ó bá jẹ́ pé mo ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, èmi ìbá ti kó ohun púpọ̀ jọ nínú oore ayé (sí ọ̀dọ̀ mi) àti pé aburú ayé ìbá tí kàn mí. Ta ni èmi bí kò ṣe olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.”

[189] (Allāhu) Òun ni Ẹni t’Ó da yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Ó sì dá aya fún un láti ara rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ̀gbádùn ìgbépọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí ọkọ súnmọ́ ìyàwó rẹ̀, tí ó sì ru ẹrù (àtọ̀) fífúyẹ́. Ó sì rù ú kiri. Nígbà tí ó sì diwọ́ disẹ̀ sínú tán, àwọn méjèèjì pe Allāhu Olúwa wọn pé: “Tí O bá fún wa ni ọmọ rere (t’ó pé ní ẹ̀dá), dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”

[190] Ṣùgbọ́n nígbà tí Allāhu fún àwọn méjèèjì ní ọmọ rere, wọ́n sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Un nípasẹ̀ ohun tí Ó fún àwọn méjèèjì. Allāhu sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I. kí ènìyàn wá sọ ọmọ náà ni “ ‘abdu-ṣṣams ‘abdul-ƙọmọr” dípò “ ‘abdullāh bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ibn Kathīr ka ìtàn náà mọ́ ara ìtàn irọ́ àwọn ọmọ Isrọ̄’īl. Àmọ́ ìtàn tí ẹnu kùn yìí kúkú ni àwọn tí wọ́n gbà pé Ànábì Ādam (alaehi sọlāt wa salām) àti ìyá wa Hawā’ (rọdiyallahu anhā) ni tọkọ tìyàwó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí rí mú lò láti fi túmọ̀ āyah náà. Kókó ìtàn náà ni pé nígbà tí ìyá wa Hawā’ (rọdiyallāhu 'anhā) lóyún àmọ́ kò forí balẹ̀ fún Èṣù rárá. Ìyẹn wà nínú ìwé Luku 4: 1-13. Nítorí náà Allāhu nìkan ṣoṣo ni kò lè ṣàṣìṣe

[191] Ṣé wọn yóò sọ n̄ǹkan tí kò lè dá n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ Rẹ̀, A sì ṣẹ̀dá wọn ni

[192] Àwọn òrìṣà kò lè ṣe àrànṣe kan fún àwọn abọ̀rìṣà. Àti pé àwọn òrìṣà gan-an kò lè ṣe àrànṣe fún ẹ̀mí ara wọ́n

[193] Tí ẹ bá pè wọ́n síbi ìmọ̀nà, wọn kò níí tẹ̀lé yín. Bákan náà ni fun yín; ẹ pè wọ́n tàbí ẹ̀yin dákẹ́ ẹnu (fún wọn)

[194] Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹrú bí irú yin ni wọ́n. Nítorí náà, ẹ pè wọ́n wò, kí wọ́n da yín lóhùn tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[195] Ṣé wọ́n ní ẹsẹ̀ tí wọ́n lè fi rìn ni? Tàbí ṣé wọ́n ní ọwọ́ tí wọ́n lè fi gbá n̄ǹkan mú? Tàbí ṣé wọ́n ní ojú tí wọ́n lè fi ríran? Tàbí ṣé wọ́n ní etí tí wọ́n lè fi gbọ́rọ̀? Sọ pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín, lẹ́yìn náà kí ẹ déte sí mi, kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára

[196] Dájúdájú Alátìlẹ́yìn mi ni Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà náà kalẹ̀. Àti pé Òun l’Ó ń ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn ẹni rere

[197] Àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe àrànṣe fun yín. Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún ẹ̀mí ara wọ́n

[198] Tí ẹ bá sì pè wọ́n sínú ìmọ̀nà, wọn kò níí gbọ́. Ò ń rí wọn pé wọ́n ń wò ọ́ ni, (ṣùgbọ́n) wọn kò ríran

[199] Ṣàmójúkúrò, pàṣẹ ohun rere, kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìmọ̀kan

[200] Tí ìbínú òdì kan bá sì ṣẹ́rí sínú ọkàn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Èṣù, sá di Allāhu. Dájúdájú Òun ní Olùgbọ́, Onímọ̀

[201] Dájúdájú àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu), nígbà tí ròyíròyí kan bá ṣẹlẹ̀ sí wọn láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí wọ́n bá rántí (Allāhu), nígbà náà ojú wọn yó sì ríran (rí òdodo)

[202] (Àmọ́ ní ti) àwọn ọmọ ìyá (Èṣù), ńṣe ni àwọn Èṣù yóò máa kún wọn lọ́wọ́ nínú ìṣìnà. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dáràn mọ níwọ̀n

[203] Nígbà tí o ò bá mú àmì wá bá wọn, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kò ṣe ṣe àdáhun rẹ̀?” Sọ pé: “Ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi ni mò ń tẹ̀lé. (al-Ƙur’ān) yìí sì ni àwọn ẹ̀rí t’ó dájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ sì ni fún àwọn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo

[204] Nígbà tí wọ́n ba ń ke al-Ƙur’ān, ẹ tẹ́tí sí i, kí ẹ sì dákẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín

[205] Ṣe ìrántí Olúwa Rẹ nínú ẹ̀mí rẹ pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ìbẹ̀rù (Allāhu), kò sì níí jẹ́ ọ̀rọ̀ ariwo, ní òwúrọ̀ àti àṣálẹ́. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn olùgbàgbéra (nípa ìrántí Allāhu)

[206] Dájúdájú àwọn t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, wọn kì í jọra wọn lójú láti jọ́sìn fún Un. Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ fún Un

Ìkógun

Surah 8

[1] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọrọ̀ ogun. Sọ pé: “Ọrọ̀ ogun jẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì ṣe àtúnṣe n̄ǹkan tí ń bẹ láààrin yín. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[2] Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi (ìyà) Allāhu ṣe ìrántí (fún wọn), ọkàn wọn yóò wárìrì, nígbà tí wọ́n bá sì ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn, wọn yóò lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé

[3] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn

[4] Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni onígbàgbọ́ òdodo. Àwọn ipò gíga, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn

[5] Gẹ́gẹ́ bí Olúwa rẹ ṣe mú ọ jáde (lọ sí ojú ogun) láti inú ilé rẹ pẹ̀lú òdodo, dájúdájú igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ ni ẹ̀mí wọn kọ̀ ọ́

[6] Wọ́n sì ń takò ọ́ níbi òdodo lẹ́yìn tí ó ti fojú hàn (sí wọn) àfi bí ẹni pé wọ́n ń wà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ikú, tí wọ́n sì ń wò ó (báyìí)

[7] (Rántí) nígbà tí Allāhu ṣàdéhùn ọ̀kan nínú àwọn ìjọ méjèèjì fun yín pé ó máa jẹ́ tiyín, ẹ̀yin sì ń fẹ́ kí ìjọ tí kò dira ogun jẹ́ tiyín. Allāhu sì fẹ́ mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Ó sì (fẹ́) pa àwọn aláìgbàgbọ́ run pátápátá

[8] nítorí kí (Allāhu) lè fi òdodo (’Islām) rinlẹ̀ ní òdodo, kí Ó sì lè paná irọ́ (ìbọ̀rìṣà), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (ọ̀ṣẹbọ) ìbáà kórira rẹ̀

[9] (Rántí) nígbà tí ẹ̀ ń wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa yín, Ó sì da yín lóhùn pé dájúdájú Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan nínú àwọn mọlāika t’ó máa wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé

[10] Allāhu kò sì ṣe (ìrànlọ́wọ́ àwọn mọlāika) lásán bí kò ṣe nítorí kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú àti nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe kan àfi láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[11] (Rántí) nígbà tí (Allāhu) ta yín ní òògbé lọ (kí ó lè jẹ́) ìfọ̀kànbalẹ̀ (fun yín) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó tún sọ omi kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀ nítorí kí Ó fi lè fọ̀ yín mọ́ (pẹ̀lú ìwẹ̀ ọ̀ran-anyàn), àti nítorí kí Ó fi lè mú èròkerò Èṣù (bí àlá ìbálòpò ojú oorun) kúrò fun yín àti nítorí kí Ó lè kì yín lọ́kàn àti nítorí kí Ó lè mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin

[12] (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ fi mọ àwọn mọlāika pé dájúdájú Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ fi ẹsẹ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀. Èmi yóò ju ẹ̀rù sínú ọkàn àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, ẹ máa gé (wọn) lókè ọrùn. Kí ẹ sì máa gé gbogbo ọmọ ìka wọn

[13] Ìyẹn nítorí pé wọ́n tako (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tako (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà

[14] Ìyẹn (nìyà tayé). Nítorí náà, ẹ tọ́ ọ wò. Àti pé dájúdájú ìyà Iná ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́

[15] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń wọ́ jáde níkọ̀ níkọ̀, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ pẹ̀yìn dà sí wọn (láti ságun)

[16] Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pẹ̀yìn dà sí wọn ní ọjọ́ yẹn, yàtọ̀ sí ẹni t’ó yẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan (láti túnra mú) fún ogun tàbí ẹni t’ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ (mùsùlùmí láti fún wọn ní ìró ọ̀tẹlẹ̀-múyẹ́), dájúdájú (aságun) ti padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé rẹ̀. Ìkángun náà sì burú

[17] Ẹ̀yin kọ́ l’ẹ pa wọ́n, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó pa wọ́n. Àti pé ìwọ kọ́ l’o jùkò nígbà tí o jùkò, àmọ́ dájúdájú Allāhu l’Ó jùkò nítorí kí (Allāhu) lè fi àmìwò dáadáa kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[18] Ìyẹn (báyẹn). Dájúdájú Allāhu máa sọ ète àwọn aláìgbàgbọ́ di lílẹ

[19] Tí ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) bá ń wá ìdájọ́, dájúdájú ìdájọ́ ti kò le yín lórí. Tí ẹ bá jáwọ́ (níbi ogun), ó sì dára jùlọ fun yín. Tí ẹ bá tún padà (síbi ogun), A máa padà (ran àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́wọ́); àkójọ yín kò sì níí rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan, ìbáà pọ̀. Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[20] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ má ṣe gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ẹ bá ń gbọ́ (āyah) lọ́wọ́

[21] Ẹ má se dà bí àwọn tí wọ́n wí pé: “A gbọ́.” Wọn kò sì gbọ́

[22] Dájúdájú ẹ̀dá abẹ̀mí t’ó burú jùlọ ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni àwọn adití, ayaya tí kò ṣe làákàyè

[23] Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu mọ oore kan lára wọn ni, ìbá jẹ́ kí wọ́n gbọ́. Tí (Allāhu) bá sì fún wọn gbọ́ ni, dájúdájú wọn máa pẹ̀yìn dà, wọn yó sì máa gbúnrí

[24] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́pè ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́, nígbà tí ó bá pè yín síbi n̄ǹkan tí ó máa mu yín ṣẹ̀mí. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń ṣèdíwọ́ láààrin ènìyàn àti ọkàn rẹ̀. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ko yín jọ sí

[25] Ẹ ṣọrá fún àdánwò kan tí kò níí mọ lórí àwọn t’ó ṣàbòsí nínú yín nìkan. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le níbi ìyà

[26] Ẹ rántí pé nígbà tí ẹ̀yin kéré, tí wọ́n ń fojú tínrín yín lórí ilẹ̀, tí ẹ sì ń páyà pé àwọn ènìyàn máa ji yín gbé lọ, nígbà náà (Allāhu) ṣe ibùgbé fun yín (nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀), Ó sì fi àrànṣe Rẹ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fun yín. Ó tún pèsè fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa nítorí kí ẹ lè dúpẹ́

[27] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jàǹbá (ọ̀ran-anyàn) Allāhu àti (sunnah) Òjíṣẹ́; ẹ má ṣe jàǹbá àwọn àgbàfipamọ́ yín, ẹ sì mọ (ìjàǹbá)

[28] Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín, àti pé dájúdájú Allāhu ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[29] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fun yín ní ọ̀nà àbáyọ. Ó máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fun yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́lá t’ó tóbi

[30] (Rántí) nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń déte sí ọ láti dè ọ́ mọ́lẹ̀ tàbí láti pa ọ́ tàbí láti yọ ọ́ kúrò nínú ìlú; wọ́n ń déte, Allāhu sì ń déte. Allāhu sì lóore jùlọ nínú àwọn adéte

[31] Nígbà tí A bá ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gbọ́. Tí ó bá jẹ́ pé a bá fẹ́ ni. àwa náà ìbá sọ irú èyí. Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

[32] (Rántí) nígbà tí wọ́n wí pé: “Allāhu, tí ó bá jẹ́ pé èyí ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ, rọ òjò òkúta lé wa lórí láti sánmọ̀ tàbí kí O mú ìyà ẹlẹ́ta-eléro kan wá bá wa.”

[33] Allāhu kò níí jẹ wọ́n níyà nígbà tí ìwọ sì ń bẹ láààrin wọn. Allāhu kò sì níí jẹ wọ́n níyà nígbà tí wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn

[34] Kò sí ìdí tí Allāhu kò fi níí jẹ wọ́n níyà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn lórí kúrò nínú Mọ́sálásí Haram. Àti pé àwọn ọ̀ṣẹbọ kọ́ ni alámòjúútó rẹ̀. Kò sí alámòjúútó kan fún un bí kò ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[35] Ìjọ́sìn àwọn ọ̀ṣẹbọ ní Ilé (Kaabah) kò sì tayọ ṣíṣú ìfé àti pípa àtẹ́wọ́. Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí pé ẹ jẹ́ aláìgbàgbọ́

[36] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n ń ná dúkìá wọn nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọ́n sì ń ná a lọ (bẹ́ẹ̀). Lẹ́yìn náà, ó máa di àbámọ̀ fún wọn. Lẹ́yìn náà, A sì máa borí wọn. Àti pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, inú iná Jahanamọ ni A máa kó wọn jọ sí

[37] nítorí kí Allāhu lè ya àwọn ẹni ibi sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹni ire àti nítorí kí Ó lè kó àwọn ẹni ibi papọ̀; apá kan wọn mọ́ apá kan, kí Ó sì lè rọ́ gbogbo wọn papọ̀ pátápátá (sójú kan náà), Ó sì máa fi wọ́n sínú iná Jahanamọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò

[38] Sọ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), A máa ṣàforíjìn ohun t’ó ti ré kọjá fún wọn. Tí wọ́n bá tún padà (síbẹ̀, àpèjúwe) ìparun àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá (ní ìkìlọ̀ fún wọn)

[39] Ẹ jà wọ́n lógun títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́, gbogbo ẹ̀sìn yó sì lè jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[40] Tí wọ́n bá sì gbúnrí (kúrò nínú ìgbàgbọ́), ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláfẹ̀yìntì yín. Ó dára ní Aláfẹ̀yìntì. Ó sì dára ní Alárànṣe

[41] Ẹ mọ̀ pé ohunkóhun tí ẹ bá kó ní ọrọ̀ ogun, dájúdájú ti Allāhu ni ìdá márùn-ún rẹ̀. Ó sì wà fún Òjíṣẹ́ àti ẹbí (rẹ̀) àti àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá), tí ẹ bá jẹ́ ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa ní Ọjọ́ ìpínyà, ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé (lójú ogun Badr). Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[42] (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀yin wà ní etí kòtò t’ó súnmọ́ (ìlú Mọdīnah), àwọn (kèfèrí) sì wà ní etí kòtò t’ó jìnnà sí (ìlú Mọdīnah), àwọn kèfèrí kan t’ó ń gun n̄ǹkan ìgùn (bọ̀ láti ìrìn-àjò òkòwò), wọ́n sì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ tiyín. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin àti àwọn kèfèrí jọ mú ọjọ́ fún ogun náà ni, ẹ̀yin ìbá yapa àdéhùn náà, ṣùgbọ́n (ogun náà ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ; nítorí kí ẹni tí ó máa parun (sínú àìgbàgbọ́) lè parun nípasẹ̀ ẹ̀rí t’ó yanjú, kí ẹni t’ó sì máa yè (nínú ìgbàgbọ́ òdodo) lè yè nípasẹ̀ ẹ̀rí t’ó yanjú. Àti pé dájúdájú Allāhu kúkú ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[43] (Rántí) nígbà tí Allāhu fi wọ́n hàn ọ́ nínú àlá rẹ (pé wọ́n) kéré. Tí ó bá jẹ́ pé Ó fi wọ́n hàn ọ́ (pé wọ́n) pọ̀ ni, ẹ̀yin ìbá ṣojo, ẹ̀yin ìbá sì ṣàríyànjiyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n Allāhu ko (yín) yọ. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[44] (Rántí) nígbà tí Ó ń fi wọ́n hàn yín pé wọ́n kéré lójú yín - nígbà tí ẹ pàdé (lójú ogun) – Ó sì mú ẹ̀yin náà kéré lójú tiwọn náà, nítorí kí Allāhu lè mú ọ̀rọ̀ kan tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ wá sí ìmúṣẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí

[45] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé ìjọ (ogun) kan, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní (òǹkà) púpọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè

[46] Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ má ṣe jara yín níyàn (nípa ogun ẹ̀sìn) nítorí kí ẹ má baà ṣojo àti nítorí kí agbára yín má baà kúrò lọ́wọ́ yín. Ẹ ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù

[47] Ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó jáde kúrò nínú ilé wọn pẹ̀lú fáààrí àti ṣekárími. Wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[48] (Rántí) nígbà tí Èṣù ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, ó sì wí pé: “Kò sí ẹni tí ó máa borí yín lónìí nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú èmi ni aládùúgbò yín.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìjọ ogun méjèèjì fojú kanra wọn, ó padà sẹ́yìn, ó sì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, ó wí pé: "Dájúdájú èmi ti yọwọ́-yọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ yín. Dájúdájú èmi ń rí ohun tí ẹ̀yin kò rí. Èmi ń pàyà Allāhu. Allāhu sì le níbi ìyà

[49] (Rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àrùn ń bẹ nínú ọkàn wọn wí pé: “Ẹ̀sìn àwọn wọ̀nyí tàn wọ́n jẹ.” Ẹnikẹ́ni t’ó bá gbáralé Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[50] Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn mọlāika bá ń gba ẹ̀mí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ni, tí wọ́n ń lu ojú wọn àti ẹ̀yìn wọn, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé), “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”

[51] Ìyẹn nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì ṣíwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀)

[52] (Ìṣesí àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn - wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu. - Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ó le níbi ìyà

[53] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà ìdẹ̀ra tí Ó ṣe fún ìjọ kan títí wọn yóò fi ṣe ìyípadà n̄ǹkan tí ń bẹ lọ́dọ̀ ara wọn. Dájúdájú Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[54] (Ìṣesí àwọn aláìmoore) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Olúwa wọn nírọ́. Nítorí náà, A pa wọ́n run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; A sì tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì sínú agbami. Gbogbo wọn sì jẹ́ alábòsí

[55] Dájúdájú ẹ̀dá abẹ̀mí t’ó burú jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́

[56] Àwọn tí o bá ṣe àdéhùn nínú wọn, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń tú àdéhùn wọn ní gbogbo ìgbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù (Allāhu)

[57] yálà tí ọwọ́ yín bá bà wọ́n lójú ogun, (ẹ pa wọ́n) kí ẹ sì (fi ogun) tú àwọn ọmọlẹ́yìn wọn ká nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[58] tàbí tí o bá sì ń páyà ìwà ìjàǹbá láti ọ̀dọ̀ ìjọ kan, ju àdéhùn wọn sílẹ̀ fún wọn kí ẹ dì jọ mọ̀ pé kò sí àdéhùn kan mọ́ láààrin ẹ̀yin méjèèjì. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn oníjàǹbá

[59] Kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé àwọn ti gbawájú. Dájúdájú wọn kò lè mórí bọ́ (nínú ìyà)

[60] Ẹ pèsè sílẹ̀ dè wọ́n n̄ǹkan ìjà tí agbára yín ká nínú n̄ǹkan àmúṣagbára àti àwọn ẹṣin orí ìso, tí ẹ̀yin yóò fi máa dẹ́rù ba ọ̀tá Allāhu àti ọ̀tá yín pẹ̀lú àwọn mìíràn yàtọ̀ sí wọn, tí ẹ̀yin kò mọ̀ wọ́n – Allāhu sì mọ̀ wọ́n. – Ohunkóhun tí ẹ bá ná lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A óò san án padà fun yín ní kíkún; A ò sì níí ṣe àbòsí fun yín

[61] Tí wọ́n bá tẹ̀ síbi (ètò) àlàáfíà (fún dídá ogun dúró), ìwọ náà tẹ̀ síbẹ̀, kí o sì gbáralé Allāhu. Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[62] Tí wọ́n bá tún fẹ́ tàn ọ́ jẹ, dájúdájú Allāhu á tó ọ. Òun ni Ẹni tí Ó fi àrànṣe Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ràn ọ́ lọ́wọ́

[63] Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Tí ó bá jẹ́ pé o ná gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá, ìwọ kò lè pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Ṣùgbọ́n Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn, dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[64] Ìwọ Ànábì, Allāhu ti tó ìwọ àti àwọn t’ó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[65] Ìwọ Ànábì, gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìyànjú lórí ogun ẹ̀sìn. Tí ogún onísùúrù bá wà nínú yín, wọn yóò borí igba. Tí ọgọ́rùn-ún bá sì wà nínú yín, wọn yóò borí ẹgbẹ̀rún nínú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé

[66] Nísisìn yìí, Allāhu ti ṣe é ní fífúyẹ́ fun yín. Ó sì mọ̀ pé dájúdájú àìlágbára ń bẹ fun yín. Nítorí náà, tí ọgọ́rùn-ún onísùúrù bá wà nínú yín, wọn yóò borí igba. Tí ẹgbẹ̀rún kan bá sì wà nínú yín, wọn yóò borí ẹgbẹ̀rún méjì pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Allāhu sì wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù

[67] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti ní ẹrú ogun (kí ó sì tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀) títí ó fi máa ṣẹ́gun (wọn) tán pátápátá lórí ilẹ̀. Ẹ̀yin ń fẹ́ ìgbádùn ayé, Allāhu sì ń fẹ́ ọ̀run. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[68] Tí kì í bá ṣe ti àkọsílẹ̀ kan t’ó ti gbawájú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni, ọwọ́ ìyà ńlá kò bá tẹ̀ yín nípa n̄ǹkan tí ẹ gbà (ní owó ìtúsílẹ̀)

[69] Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí ẹ kó ní ọrọ̀ ogun (tí ó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti) n̄ǹkan dáadáa. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[70] Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn t’ó ń bẹ lọ́wọ́ yín nínú àwọn ẹrú ogun pé, “Tí Allāhu bá mọ dáadáa kan nínú ọkàn yín, Ó máa fun yín ní ohun t’ó dára ju ohun tí wọ́n gbà lọ́wọ́ yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.”

[71] Tí wọ́n bá sì ń gbèrò ìjàǹbá sí ọ, wọ́n kúkú ti jàǹbá Allāhu ṣíwájú. Ó sì fún ọ lágbára lórí wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[72] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, àti àwọn t’ó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; àwọn wọ̀nyẹn, apá kan wọn l’ọ̀rẹ́ apá kan (t’ó lè jogún ara wọn). Àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọn kò sì gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fun yín láti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ níbì kan kan (t’ó lè mu yín jogún ara yín), títí wọn yóò fi gbé ìlú wọn jù sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ yín (lórí ọ̀tá) nípa ẹ̀sìn, ìrànlọ́wọ́ náà di dandan fun yín àyàfi lórí ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[73] Àwọn aláìgbàgbọ́; apá kan wọn ni alátìlẹ́yìn apá kan. Àfi kí ẹ̀yin náà ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìfòòró àti ìbàjẹ́ t’ó tóbi kò fi níí wà lórí ilẹ̀

[74] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì jagun l’ójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti àwọn t’ó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; ní ti òdodo àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onígbàgbọ́ òdodo. Àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé sì wà fún wọn

[75] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo lẹ́yìn (wọn), tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú yín, àwọn wọ̀nyẹn náà wà lára yín. Àti pé àwọn ìbátan, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí apá kan (nípa ogún jíjẹ) nínú Tírà Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

Ìrònúpìwàdà

Surah 9

[1] (Èyí ni) ìyọwọ́-yọsẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn tí ẹ ṣe àdéhùn fún nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ

[2] Nítorí náà, (ẹ̀yin ọ̀ṣẹbọ) ẹ rìn (kiri) lórí ilẹ fún oṣù mẹ́rin. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀yin kò lè móríbọ́ (nínú ìyà) Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu yóò dójú ti àwọn aláìgbàgbọ́

[3] Ìkéde kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ní ọjọ́ Hajj Ńlá ni pé, “Dájúdájú Allāhu yọwọ́yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀) àwọn ọ̀ṣẹbọ. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ náà (yọwọ́yọsẹ̀). Tí ẹ bá ronú pìwàdà, ó sì lóore jùlọ fun yín. Tí ẹ bá gbúnrí, ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ ò lè móríbọ́ nínú (ìyà) Allāhu.” Kí o sì fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[4] Àyàfi àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, lẹ́yìn náà, tí wọn kò sì fi ọ̀nà kan kan yẹ àdéhùn yín, tí wọn kò sì ṣàtìlẹ́yìn fún ẹnì kan kan le yín lórí. Nítorí náà, ẹ pé àdéhùn wọn fún wọn títí di àsìkò wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[5] Nítorí náà, nígbà tí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ bá lọ tán , ẹ pa àwọn ọ̀ṣẹbọ níbikíbi tí ẹ bá ti bá wọn. Ẹ mú wọn, ẹ ṣéde mọ́ wọn, kí ẹ sì ba dè wọ́n ní gbogbo ibùba. Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, ẹ yàgò fún wọn lójú ọ̀nà. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[6] Tí ẹnì kan nínú àwọn ọ̀sẹbọ bá wá ètò ààbò wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣ’ètò ààbò fún un títí ó fi máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, mú u dé àyè ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò nímọ̀

[7] Báwo ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́dọ̀ Allāhu àti lọ́dọ̀ Òjísẹ́ Rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nítòsí Mọ́sálásí Haram? Nítorí náà, tí wọ́n bá dúró déédé pẹ̀lú yín, ẹ dúró déédé pẹ̀lú wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[8] Báwo (ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún wọn) nígbà tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá borí yín, wọn kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn. Wọ́n ń fi ẹnu wọn wí pé àwọn yọ́nú si yín, ọkàn wọn sì kọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́

[9] Wọ́n ta àwọn āyah Allāhu ní owó pọ́ọ́kú, wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Dájúdájú àwọn (wọ̀nyí), ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú

[10] Àwọn ọ̀ṣẹbọ kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn kan fún onígbàgbọ́ òdodo kan. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùtayọ ẹnu-àlà

[11] Nítorí náà, tí wọ́n bá ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, nígbà náà ọmọ-ìyá yín nínú ẹ̀sìn ni wọ́n. À ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún ìjọ t’ó nímọ̀

[12] Tí wọ́n bá rú ìbúra wọn lẹ́yìn àdéhùn wọn, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àìdara sí ẹ̀sìn yín, nígbà náà ẹ ja àwọn olórí aláìgbàgbọ́ lógun - dájúdájú ìbúra wọn kò ní ìtúmọ̀ kan sí wọn – kí wọ́n lè jáwọ́ (níbi aburú)

[13] Ṣé ẹ ò níí gbógun ti ìjọ kan t’o rú ìbúra wọn, tí wọ́n sì gbèrò láti lé Òjíṣẹ́ kúrò (nínú ìlú); àwọn sì ni wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbógun tì yín ní ìgbà àkọ́kọ́? Ṣé ẹ̀ ń páyà wọn ni? Allāhu l’Ó ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí pé kí ẹ páyà Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[14] Ẹ jà wọ́n lógun. Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà láti ọwọ́ yín. Ó máa yẹpẹrẹ wọn. Ó máa ràn yín lọ́wọ́ lórí wọn. Ó sì máa wo ọkàn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo sàn

[15] Ó tún máa kó ìbínú ọkàn wọn lọ. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[16] Tàbí ẹ lérò pé A óò fi yín sílẹ̀ láì jẹ́ pé Allāhu ti ṣàfi hàn àwọn t’ó máa jagun ẹ̀sìn nínú yín, tí wọn kò sì ní ọ̀rẹ́ àyò kan lẹ́yìn Allāhu, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo? Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[17] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti ṣe àmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu, nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àìgbàgbọ́ lórí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Iná

[18] Ẹni tí ó máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu ni ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, t’ó sì ń kírun, t’ó ń yọ Zakāh, kò sì páyà (òrìṣà kan) lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n kúkú wà nínú àwọn olùmọ̀nà

[19] Ṣé ẹ máa ṣe fífún alálàájì ní omi mu àti ṣíṣe àmójútó Mọ́sálásí Haram ní ohun t’ó dọ́gba sí ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, t’ó sì jagun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu? Wọn kò dọ́gba lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[20] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu, wọ́n tóbi jùlọ ní ipò lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè

[21] Olúwa wọn ń fún wọn ní ìró ìdùnnú nípa ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ́nú àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí ìdẹ̀ra gbére wà fún wọn nínú rẹ̀

[22] Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ẹ̀san ńlá wà

[23] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn bàbá yín àti àwọn arakùnrin yín ní ọ̀rẹ́ àyò bí wọ́n bá gbọ́lá fún àìgbàgbọ́ lórí ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni t’ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí

[24] Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn bàbá yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn arákùnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ìbátan yín pẹ̀lú àwọn dúkìá kan tí ẹ ti kó jọ àti òkòwò kan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù pé kí ó má kùtà àti àwọn ibùgbé tí ẹ yọ́nú sí, (tí ìwọ̀nyí) bá wù yín ju Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú jíja ogun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀, ẹ máa retí (ìkángun) nígbà náà títí Allāhu yóò fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[25] Dájúdájú Allāhu ti ṣe àrànṣe fun yín ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ojú ogun àti ní ọjọ́ (ogun) Hunaen, nígbà tí pípọ̀ yín jọ yín lójú, (àmọ́) kò rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan; ilẹ̀ sì fún mọ yín tòhun ti bí ó ṣe fẹ̀ tó. Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìn dà, ẹ sì ń sá sẹ́yìn

[26] Lẹ́yìn náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó tún sọ àwọn ọmọ ogun kan kalẹ̀, tí ẹ ò fojú rí wọn. Ó sì jẹ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ níyà. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́

[27] Lẹ́yìn náà, Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́ lẹ́yìn ìyẹn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[28] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ẹ̀gbin ni àwọn ọ̀sẹbọ. Nítorí náà, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ Mọ́sálásí Haram lẹ́yìn ọdún wọn yìí. Tí ẹ bá ń bẹ̀rù òṣì, láìpẹ́ Allāhu máa rọ̀ yín lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀, tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[29] Ẹ gbógun ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn tí kò ṣe ní èèwọ̀ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀ àti àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn òdodo nínú àwọn tí A fún ní tírà. (Ẹ gbógun tì wọ́n) títí wọ́n yóò fi máa fi ọwọ́ ará wọn san owó-orí ní ẹni yẹpẹrẹ

[30] Àwọn yẹhudi wí pé: "‘Uzaer ni ọmọ Allāhu." Àwọn nasara sì wí pé: "Mọsīh ni ọmọ Allāhu." Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ wọn ní ẹnu wọn. Wọ́n ń fi jọ ọ̀rọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ṣíwájú (wọn). Allāhu fi wọ́n gégùn-ún. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo

[31] Wọ́n mú àwọn àlùfáà wọn (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà wọn (nínú nasara) ní olúwa lẹ́yìn Allāhu. (Wọ́n tún mú) Mọsīh ọmọ Mọryam (ní olúwa lẹ́yìn Allāhu). Bẹ́ẹ̀ sì ni A ò pa wọ́n láṣẹ kan tayọ jíjọ́sìn fún Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó mọ́ tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[32] Wọ́n fẹ́ fi ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Allāhu, Allāhu yó sì kọ̀ (fún wọn) títí Ó fi máa pé ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Rẹ̀, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀

[33] (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (ẹ̀sìn ’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀

[34] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà (nínú nasara), wọ́n kúkú ń fi ọ̀nà èrú jẹ dúkìá àwọn ènìyàn ni, wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àwọn t’ó sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ, wọn kò sì ná an fún ẹ̀sìn Allāhu, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[35] Ní ọjọ́ tí A óò máa yọ́ (wúrà àti fàdákà náà) nínú iná Jahanamọ, A ó sì máa fi jó iwájú wọn, ẹ̀gbẹ́ wọn àti ẹ̀yìn wọn. (A sì máa sọ pé): "Èyí ni ohun tí ẹ kó jọ fún ẹ̀mí ara yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ohun tí ẹ kó jọ wò

[36] Dájúdájú òǹkà àwọn oṣù lọ́dọ̀ Allāhu ń jẹ́ oṣù méjìlá nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu ní ọjọ́ tí Ó ti dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Mẹ́rin ni oṣù ọ̀wọ̀ nínú rẹ̀. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣàbòsí sí ara yín nínú àwọn oṣù ọ̀wọ̀. Kí gbogbo yín sì gbógun ti àwọn ọ̀ṣẹbọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo wọn ṣe ń gbógun tì yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[37] Àlékún nínú àìgbàgbọ́ ni dídájọ́ sí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ (láti ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ). Wọ́n ń fi kó ìṣìnà bá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (nípa pé) wọ́n ń ṣe oṣù ọ̀wọ̀ kan ní oṣù ẹ̀tọ́ (fún ogun jíjà) nínú ọdún kan, wọ́n sì ń bu ọ̀wọ̀ fún oṣù (tí kì í ṣe oṣù ọ̀wọ̀) nínú ọdún (mìíràn, wọn kò sì níí jagun nínú rẹ̀) nítorí kí wọ́n lè yọ òǹkà oṣù tí Allāhu ṣe ní ọ̀wọ̀ síra wọn. Wọ́n sì tipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ní ẹ̀tọ́ ohun tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀. Wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́

[38] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí ni ó mu yín tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí A bá sọ fun yín pé kí ẹ jáde (láti jagun) lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, (ìgbà náà ni) ẹ máa kàndí mọ́lẹ̀! Ṣé ẹ yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ju ti ọ̀run ni? Ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé (yìí) kò sì jẹ́ kiní kan nínú ti ọ̀run àfi díẹ̀

[39] Àfi kí ẹ tú jáde (sógun ẹ̀sìn) ni Allāhu kò fi níí jẹ yín níyà ẹlẹ́ta-eléro àti pé ni kò fi níí fi ìjọ tó yàtọ̀ si yín pààrọ̀ yín. Ẹ kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá (Allāhu). Allāhu sì ni Alagbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[40] Àfi kí ẹ ràn án lọ́wọ́, Allāhu kúkú ti ràn án lọ́wọ́ nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lé e jáde (kúrò nínú ìlú). Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì.1 Nígbà tí àwọn méjèèjì wà nínú ọ̀gbun, tí (Ànábì) sì ń sọ fún olùbárìn rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú wa."2 Nígbà náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún un. Ó fi àwọn ọmọ ogun kan tí ẹ ò fojú rí ràn án lọ́wọ́. Ó sì mú ọ̀rọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wálẹ̀. Ọ̀rọ̀ Allāhu, òhun l’ó sì lékè. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[41] Ẹ tú jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú okun àti ìrọ́jú. Kí ẹ sì fi àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yin jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀

[42] Tí ó bá jẹ́ pé n̄ǹkan ìgbádùn (ọrọ̀ ogun) àrọ́wótó àti ìrìn-àjò tí kò jìnnà (l’o pè wọ́n sí ni), wọn ìbá tẹ̀lé ọ. Ṣùgbọ́n ìrìn-àjò ogun Tabūk jìnnà lójú wọn. Wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a lágbára ni, àwa ìbá jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú yín.” – Wọ́n sì ń kó ìparun bá ẹ̀mí ara wọn (nípa ṣíṣe ìṣọ̀bẹ-ṣèlu.) – Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọn

[43] Allāhu ti ṣàmójúkúrò fún ọ. Kí ló mú ọ yọ̀ǹda fún wọn (pé kí wọ́n dúró sílé? Ìwọ ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀) títí ọ̀rọ̀ àwọn t’ó sòdodo yóò fi hàn sí ọ kedere. Ìwọ yó sì mọ àwọn òpùrọ́

[44] Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kò níí tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ láti má fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[45] Àwọn t’ó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, dípò lílọ sí ojú-ogun) ni àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ọkan wọn sì ń ṣeyèméjì. Nítorí náà, wọ́n ń dààmú kiri níbi ìṣeyè-méjì wọn

[46] Tí ó bá jẹ́ pé wọn gbèrò ìjáde fún ogun ẹ̀sìn ni, wọn ìbá ṣe ìpalẹ̀mọ́ fún un. Ṣùgbọ́n Allāhu kórira ìdìde wọn fún ogun ẹ̀sìn, Ó sì kó ìfàsẹ́yìn bá wọn. Wọ́n sì sọ fún wọn pé: "Ẹ jókòó pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé

[47] Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n jáde pẹ̀lú yín, wọn kò níí kun yín àfi pẹ̀lú ìbàjẹ́. Wọn yó sì sáré máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láààrin yín, tí wọn yóò máa ko yín sínú ìyọnu. Àti pé wọ́n ní olùgbọ́rọ̀ fún wọn láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí

[48] Wọ́n kúkú ti dá ìyọnu sílẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Wọ́n sì dojú àwọn ọ̀rọ̀ rú fún ọ títí òdodo fi dé, tí àṣẹ Allāhu sì fojú hàn kedere; ẹ̀mí wọn sì kọ̀ ọ́

[49] Ó wà nínú wọn, ẹni tí ń wí pé: “Yọ̀ǹda fún mi (kí n̄g jókòó sílé); má ṣe kó mi sínú àdánwò.” Inú àdánwò (sísá fógun ẹ̀sìn) má ni wọ́n ti ṣubú sí yìí. Dájúdájú iná Jahanamọ yó sì kúkú yí àwọn aláìgbàgbọ́ po

[50] Tí dáadáa bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó máa bà wọ́n nínú jẹ́. Tí àìda bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gba àṣẹ tiwa ṣíwájú (láti jókòó sílé.)” Wọ́n á pẹ̀yìn dà; wọn yó sì máa dunnú

[51] Sọ pé: “Kò sí ohun kan t’ó máa ṣẹlẹ̀ sí wa àyàfi ohun tí Allāhu kọ mọ́ wa. Òun ni Aláàbò wa.” Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé

[52] Sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń retí kiní kan pẹ̀lú wa ni bí kò ṣe ọ̀kan nínú dáadáa méjì (ikú ogun tàbí ìṣẹ́gun)? Àwa náà ń retí pẹ̀lú yín pé kí Allāhu mú ìyà kan wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tàbí láti ọwọ́ wa. Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú àwa náà wà pẹ̀lú yín tí à ń retí

[53] Sọ pé: "Ẹ fínnú-fíndọ̀ náwó ni tàbí pẹ̀lú tipátipá, A ò níí gbà á lọ́wọ́ yín (nítorí pé) dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[54] Kò sì sí ohun kan tí kò jẹ́ kí Á gba ìnáwó wọn lọ́wọ́ wọn bí kò ṣe pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọn kò níí wá kírun àfi kí wọ́n jẹ́ òròjú aláìníkan-ánṣe. Wọn kò sì níí náwó fẹ́sìn àfi kí ẹ̀mí wọn kọ̀ ọ́

[55] Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn yà ọ́ lẹ́nu; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. Ẹ̀mí yó sì bọ́ lára wọn, tí wọ́n máa wà nípò aláìgbàgbọ́

[56] Wọ́n ń fi Allāhu búra pé dájúdájú àwọn kúkú wà lára yín. Wọn kò sì sí lára yín, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ kan t’ó ń bẹ̀rù

[57] Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n rí ibùsásí kan, tàbí àwọn ihò àpáta kan, tàbí ibùsáwọ̀ kan, wọn ìbá ṣẹ́rí síbẹ̀ ní wéréwéré

[58] Ó tún wà nínú wọn, ẹni tí ń dá ọ lẹ́bi níbi (pípín) àwọn ọrẹ. Tí A bá fún wọn nínú rẹ̀, wọ́n á yọ́nú (sí i). Tí A ò bá sì fún wọn nínú rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa bínú

[59] Àti pé (ìbá lóore fún wọn) tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n yọ́nú sí ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì sọ pé: "Allāhu tó wa. Allāhu yó sì fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀ àti pé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sì máa pín ọrẹ) , dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àwa ń wá oore sí

[60] Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù, àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām, àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn t’ó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[61] Àwọn t’ó ń kó ìnira bá Ànábì wà nínú wọn, tí wọ́n sì ń wí pé: “Elétí-ọfẹ ni." Sọ pé: "Elétí-ọfẹ rere ni fun yín; ó gbàgbọ́ nínú Allāhu. Ó sì gbà àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbọ́. Ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nínú Òjíṣẹ́ Allāhu, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn.”

[62] Wọ́n ń fi Allāhu búra fun yín láti wá ìyọ́nú yín. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ l’ó sì yẹ kí wọ́n wá ìyọ́nú Rẹ̀ tí wọ́n bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[63] Ṣé wọn kò mọ̀ pé ẹnikẹ́ni t’ó bá ń tako Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un ni? Olùṣegbére sì ni nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni àbùkù ńlá

[64] Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bẹ̀rù pé kí Á má ṣe sọ sūrah kan kalẹ̀ nípa wọn, tí ó máa fún wọn ní ìró ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Sọ pé: "Ẹ máa ṣe yẹ̀yẹ́ lọ. Dájúdájú Allāhu yóò ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù

[65] Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè, dájúdájú wọ́n á wí pé: "Àwa kàn ń rojọ́ lásán ni, a sì ń ṣàwàdà ni." Sọ pé: "Ṣé Allāhu, àwọn āyah Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ẹ̀ ń fi ṣe yẹ̀yẹ́

[66] Ẹ má ṣe mú àwáwí wá. Dájúdájú ẹ ti ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín. Tí A bá ṣe àmójúkúrò fún apá kan nínú yín, A óò fìyà jẹ apá kan nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀

[67] Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin, irú kan-ùn ni wọ́n; wọ́n ń pàṣẹ ohun burúkú, wọ́n ń kọ ohun rere, wọ́n sì ń káwọ́ gbera (láti náwó fẹ́sìn). Wọ́n gbàgbé Allāhu. Nítorí náà, Allāhu gbàgbé wọn. Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́

[68] Allāhu sì ti ṣe àdéhùn iná Jahanamọ fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin àti àwọn aláìgbàgbọ́. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀. Iná máa tó wọn. Allāhu sì ti ṣẹ́bi lé wọn. Ìyà gbére sì wà fún wọn

[69] (Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí dà) gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú yín; wọ́n le jù yín lọ ní agbára, wọ́n sì pọ̀ (jù yín lọ) ní àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Nígbà náà, wọ́n jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn (nínú oore ayé). Ẹ̀yin (ṣọ̀bẹ-ṣèlu wọ̀nyìí náà yóò) jẹ ìgbádùn ìpín tiyín gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú yín ṣe jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn. Ẹ̀yin náà sì sọ̀sọkúsọ bí èyí tí àwọn náà sọ ní ìsọkúsọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni ẹni òfò

[70] Ṣé ìròyìn àwọn t’ó ṣíwájú wọn kò tì í dé bá wọn ni? (Ìròyìn) ìjọ (Ànábì) Nūh, ìran ‘Ād, ìran Thamūd, ìjọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn ará Mọdyan àti àwọn ìlú tí A dojú rẹ̀ bolẹ̀ (ìjọ Ànábì Lūt); àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. Nítorí náà, Allāhu kò ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ṣàbòsí sí

[71] Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan; wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n ń kírun, wọ́n ń yọ Zakāh, wọ́n sì ń tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò ṣàkẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[72] Allāhu ṣe àdéhùn àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó tún ṣe àdéhùn) àwọn ibùgbé t’ó dára nínú àwọn ọgbà ìdẹ̀ra ‘Adni (fún wọn). Ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó sì tóbi jùlọ (fún wọn). Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá

[73] Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú

[74] Wọ́n ń fi Allāhu búra pé àwọn kò sọ̀rọ̀ (burúkú). Wọ́n sì kúkú ti sọ ọ̀rọ̀ àìgbàgbọ́, wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ’Islām. Wọ́n tún gbèròkérò sí n̄ǹkan tí ọwọ́ wọn kò níí bà. Wọn kò tako kiní kan bí kò ṣe nítorí pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rọ àwọn (Sọhābah) lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Tí wọ́n bá ronú pìwàdà, ó máa dára fún wọn. Tí wọ́n bá sì kọ̀yìn (si yín), Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn lórí ilẹ̀ ayé

[75] Ó wà nínú wọn, ẹni t’ó bá Allāhu ṣe àdéhùn pé: "Tí Ó bá fún wa nínú oore-àjùlọ Rẹ̀, dájúdájú a óò máa tọrẹ, dájúdájú a ó sì wà nínú àwọn ẹni ire

[76] Àmọ́ nígbà tí Ó fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀, wọ́n ṣahun sí I. Wọ́n pẹ̀yìn dà, wọ́n sì ń gbúnrí (láti náwó fẹ́sìn)

[77] Nítorí náà, ahun wọn mú ọ̀rọ̀ wọn kángun sí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ọkàn wọn títí di ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Allāhu nítorí pé wọ́n yẹ àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe àti nítorí pé wọ́n ń parọ́

[78] Ṣé wọn kò mọ̀ pé Allāhu mọ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ wọn, àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀

[79] Àwọn t’ó ń bú àwọn olùtọrẹ-àánú nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lórí ọrẹ títa àti àwọn tí kò rí n̄ǹkan kan tayọ ìwọ̀n agbára wọn, wọ́n sì ń fi wọn ṣe yẹ̀yẹ́, Allāhu fi àwọn náà ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[80] Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn – kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin – Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[81] Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn dunnú sí jíjókòó sínú ilé wọn lẹ́yìn Òjíṣẹ́ Allāhu. Wọ́n sì kórira láti fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọ́n tún wí pé: “Ẹ má lọ jagun nínú ooru gbígbóná.” Sọ pé: “Iná Jahanamọ le jùlọ ní gbígbóná, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀.”

[82] Nítorí náà, kí wọ́n rẹ́rìn-ín díẹ̀, kí wọ́n sì sunkún púpọ̀; (ó jẹ́) ẹ̀san (fún) ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[83] Tí Allāhu bá mú ọ délé bá igun kan nínú wọn, tí wọ́n bá wá ń gbàṣẹ lọ́dọ̀ rẹ fún jíjáde fún ogun ẹ̀sìn, sọ nígbà náà pé: “Ẹ̀yin kò lè jáde fún ogun ẹ̀sìn mọ́ pẹ̀lú mi. Ẹ̀yin kò sì lè ja ọ̀tá kan lógun mọ́ pẹ̀lú mi, nítorí pé ẹ ti yọ́nú sí ìjókòó sílé ní ìgbà àkọ́kọ́. Nítorí náà, ẹ jókòó sílé ti àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn.”

[84] Láéláé, o ò gbọdọ̀ kírun sí ẹnì kan kan lára nínú wọn, tí ó bá kú, o ò sì gbọdọ̀ dúró níbi sàréè rẹ̀, nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n wà nípò òbìlẹ̀jẹ́

[85] Má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn yà ọ́ lẹ́nu; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. (Ó sì fẹ́ kí) ẹ̀mí bọ́ lára wọn, nígbà tí wọ́n bá wà nípò aláìgbàgbọ́

[86] Nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀ pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí wọ́n sí jagun pẹ̀lú Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (nígbà náà ni) àwọn ọlọ́rọ̀ nínú wọn yóò máa tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n á sì wí pé: “Fi wá sílẹ̀ kí á wà pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé.”

[87] Wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. A ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò níí gbọ́ àgbọ́yé

[88] Ṣùgbọ́n Òjíṣẹ́ àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn oore ń bẹ fún wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè

[89] Allāhu ti pèsè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá

[90] Àwọn aláwàáwí nínú àwọn Lárúbáwá oko wá (bá ọ) nítorí kí wọ́n lè yọ̀ǹda (ìjókòó sílé) fún wọn. Àwọn t’ó sì pe ọ̀rọ̀ Allāhu àti ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ nírọ́ náà jókòó sílé. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ ba àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn

[91] Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn aláìlágbára, àwọn aláìsàn àti àwọn tí kò rí ohun tí wọn máa ná ní owó (láti fi jagun ẹ̀sìn) nígbà tí wọ́n bá ti ní òtítọ́ sí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kò sí ìbáwí kan fún àwọn olótìítọ́-inú sẹ́. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[92] Kò tún sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ pé kí o fún àwọn ní n̄ǹkan tí àwọn yóò gùn (lọ sójú ogun), tí o sì sọ pé, “N̄g ò rí n̄ǹkan tí mo lè fun yín gùn (lọ sójú ogun), wọ́n máa padà pẹ̀lú ojú wọn tí yóò máa damije ní ti ìbànújẹ́ pé wọn kò rí n̄ǹkan tí wọ́n máa ná (lọ sójú ogun ẹ̀sìn)

[93] Àwọn tí ìbáwí wà fún ni àwọn t’ó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, tí) wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rọ̀, tí wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò sì mọ̀

[94] Wọ́n yóò mú àwáwí wá fun yín nígbà tí ẹ bá darí dé bá wọn. Sọ pé: "Ẹ má ṣe mú àwáwí wá; a ò níí gbà yín gbọ́. Allāhu kúkú ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yín fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yó sì rí iṣẹ́ (ọwọ́) yín. Lẹ́yìn náà, A óò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nígbà náà, Ó máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[95] Wọ́n yóò máa fi Allāhu búra fun yín nígbà tí ẹ bá darí dé bá wọn, nítorí kí ẹ lè pa wọ́n tì. Nítorí náà, ẹ pa wọ́n tì; dájúdájú ẹ̀gbin ni wọ́n. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé wọn. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[96] Wọ́n yóò máa búra fun yín nítorí kí ẹ lè yọ́nú sí wọn. Tí ẹ bá yọ́nú sí wọn, dájúdájú Allāhu kò níí yọ́nú sí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[97] Àwọn Lárúbáwá oko le nínú àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu. Ó sì súnmọ́ pé wọ́n kò mọ àwọn ẹnu-àlà ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[98] Àti pé ó wà nínú àwọn Lárúbáwá oko ẹni tí ó ka ìnáwó t’ó ń ná (fún ẹ̀sìn) sí owó ọ̀ràn. Ó sì ń retí àpadàsí aburú fun yín. Àwọn sì ni àpadàsí aburú yóò dé bá. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[99] Ó tún wà nínú àwọn Lárúbáwá oko, ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì sọ ìnáwó t’ó ń ná (fún ẹ̀sìn) di àwọn ìsúnmọ́ Allāhu àti (gbígba) àdùá (lọ́dọ̀) Òjíṣẹ́. Kíyè sí i, dájúdájú òhun ni ìsúnmọ́ Allāhu fún wọn. Allāhu yó sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[100] Àwọn aṣíwájú, àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r pẹlú àwọn t’ó fi dáadáa tẹ̀lé wọn, Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ó tún pa lésè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ títí láéláé. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá

[101] Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kan ń bẹ nínú àwọn tí ó wà ní àyíká yín nínú àwọn Lárúbáwá oko àti nínú àwọn ará ìlú Mọdīnah, tí wọ́n won̄koko mọ́ ìṣọ̀bẹ-ṣèlú. O ò mọ̀ wọ́n, Àwa l’A mọ̀ wọ́n. A óò jẹ wọ́n níyà ní ẹ̀ẹ̀ mejì. Lẹ́yìn náà, A óò dá wọn padà sínú ìyà ńlá

[102] Àwọn mìíràn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọ́n da iṣẹ́ rere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ mìíràn t’ó burú. Bóyá Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[103] Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[104] Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu Òun l’Ó ń gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, Ó sì ń gba àwọn ọrẹ, àti pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[105] Sọ pé: "Ẹ ṣiṣẹ́. Allāhu á rí iṣẹ́ yín, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (máa rí i). Wọ́n sì máa da yín padà sọ́dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[106] Wọ́n so ọ̀rọ̀ àwọn yòókù rọ̀ ná fún àṣẹ Allāhu; yálà kí Ó jẹ wọ́n níyà tàbí kí Ó gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[107] Àwọn t’ó kọ́ mọ́sálásí láti fi dá ìnira àti àìgbàgbọ́ sílẹ̀ àti láti fi ṣe òpínyà láààrin àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti láti fi ṣe ibùba fún àwọn t’ó gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní ìṣaájú – dájúdájú wọ́n ń búra pé “A ò gbèrò kiní kan bí kò ṣe ohun rere.” – Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n

[108] Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé. Dájúdájú mọ́sálásí tí wọ́n bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu láti ọjọ́ àkọ́kọ́ l’o lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o dúró (kírun) nínú rẹ̀. Àwọn ènìyàn t’ó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe ìmọ́ra wà nínú rẹ̀. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣèmọ́ra

[109] Ǹjẹ́ ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu àti ìyọ́nú (Rẹ̀) l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kan létí ọ̀gbun t’ó máa yẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì máa yẹ̀ ẹ́ lẹ́sẹ̀ sínú iná Jahanamọ? Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[110] Ilé wọn tí wọ́n mọ kalẹ̀ kò níí yé kó iyèméjì sínú ọkàn wọn títí ọkàn wọn yóò fi já kélekèle. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[111] Dájúdájú Allāhu ra ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti dúkìá wọn nítorí pé dájúdájú tiwọn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n ń jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; wọ́n ń pa ọ̀tá ẹ̀sìn, wọ́n sì ń pa àwọn náà. (Ó jẹ́) àdéhùn lọ́dọ̀ Allāhu. (Ó jẹ́) òdodo nínú at-Taorāh, al-’Injīl àti al-Ƙur’ān. Ta sì ni ó lè mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ ju Allāhu? Nítorí náà, ẹ dunnú sí òkòwò yín tí ẹ (fi ẹ̀mí àti dúkìá yin) ṣe. Ìyẹn, òhun sì ni èrèǹjẹ ńlá

[112] Àwọn olùronúpìwàdà, àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu), àwọn olùdúpẹ́ (fún Allāhu), àwọn aláààwẹ̀, àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun), àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Allāhu), àwọn olùpàṣẹ-ohun rere, àwọn olùkọ-ohun burúkú àti àwọn olùṣọ́-ẹnu-àlà tí Allāhu gbékalẹ̀, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo (wọ̀nyí) ní ìró ìdùnnú (Ọgbà Ìdẹ̀ra)

[113] Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n

[114] Àti pé àforíjìn tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm tọrọ fún bàbá rẹ̀ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe nítorí àdéhùn t’ó ṣe fún un. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó hàn sí i pé dájúdájú ọ̀tá Allāhu ni (bàbá rẹ̀), ó yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni olùrawọ́rasẹ̀, olùfaradà

[115] Allāhu kì í mú ìṣìnà bá ìjọ kan, lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti tọ́ wọn sọ́nà, títí (Allāhu) yóò fi ṣe àlàyé n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣọ́ra fún fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[116] Dájúdájú Allāhu l’ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu

[117] Dájúdájú Allāhu ti gba ìronúpìwàdà Ànábì, àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r, àwọn t’ó tẹ̀lé e ní àkókò ìṣòro lẹ́yìn tí ọkàn ìgun kan nínú wọn fẹ́ẹ̀ yí padà, (àmọ́) lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Òun ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fún wọn

[118] (Ó tún gba ìronúpìwàdà) àwọn mẹ́ta tí A (so ọ̀rọ̀ wọn rọ̀ nínú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Tabūk. Àwọn mùsùlùmí sì dẹ́yẹ sí wọn) títí ilẹ̀ fi há mọ́ wọn tòhun ti bí ó ṣe fẹjú tó. Ọ̀rọ̀ ara wọn sì ṣú ara wọn. Wọ́n sì mọ̀ (ní àmọ̀dájú) pé kò sí ibùsásí kan tí àwọn fi lè sá mọ́ Allāhu lọ́wọ́ àfi kí wọ́n sá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn nítorí kí wọ́n lè máa ronú pìwàdà. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[119] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wà pẹ̀lú àwọn olódodo

[120] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ará ìlú Mọdīnah àti ẹni tí ó wà ní àyíká wọn nínú àwọn Lárúbáwá oko láti sá sẹ́yìn fún Òjíṣẹ́ Allāhu (nípa ogun ẹ̀sìn. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn) láti fẹ́ràn ẹ̀mí ara wọn ju ẹ̀mí rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú òǹgbẹ, ìnira tàbí ebi kan kò níí ṣẹlẹ̀ sí wọn lójú ogun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tàbí wọn kò níí tẹ ọ̀nà kan tí ń bí àwọn aláìgbàgbọ́ nínú, tàbí ọwọ́ wọn kò níí ba kiní kan lára ọ̀tá àfi kí Á fi kọ iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre

[121] Wọn kò sì níí ná owó kékeré tàbí púpọ̀ (fún ogun ẹ̀sìn), tàbí kí wọ́n la àfonífojì kan kọ já àfi kí Á kọ ọ́ sílẹ̀ fún wọn nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san t’ó dára jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[122] Gbogbo àwọn mùsùlùmí kò sì gbọdọ̀ dà lọ sí ojú ogun ẹ̀sìn. Ìbá ṣuwọ̀n kí igun kan nínú wọn nínú ikọ̀ kọ̀ọ̀kan jáde láti wá àgbọ́yé nípa ẹ̀sìn, kí wọ́n sì máa ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn wọn nígbà tí wọ́n bá padà sọ́dọ̀ wọn bóyá wọn yó lè ṣọ́ra ṣe

[123] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbógun ti àwọn t’ó súnmọ́ yín nínú àwọn aláìgbàgbọ́; kí wọ́n rí ìlekoko lára yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[124] Nígbà tí A bá sì sọ sūrah kan kalẹ̀, ó ń bẹ nínú wọn ẹni tí ó máa wí pé: “Ta ni nínú yín ni èyí lé ìgbàgbọ́ (rẹ̀) kún?” Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, (āyah náà) yó sì lé ìgbàgbọ́ (wọn) kún. Wọn yó sì máa dunnú

[125] Ní ti àwọn tí àìsàn sì wà nínú ọkàn wọn, (āyah náà) yó sì ṣe àlékún ẹ̀gbin sí ẹ̀gbin wọn. Wọn yó sì kú sí ipò aláìgbàgbọ́

[126] Ṣé wọn kò rí i pé À ń dán wọn wò ní ẹ̀ẹ̀ kan tàbí ẹ̀ẹ̀ méjì ní ọdọọdún. Lẹ́yìn náà, wọn kò ronú pìwàdà, wọn kò sì lo ìrántí

[127] Àti pé nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀, apá kan wọn yóò wo apá kan lójú (wọn yó sì wí pé): “Ṣé ẹnì kan ń wò yín bí?” Lẹ́yìn náà, wọ́n máa pẹ̀yìndà. Allāhu sì pa ọkàn wọn dà (sódì) nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ kan tí kò gbọ́ àgbọ́yé

[128] Dájúdájú Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín láti ààrin yín. Ohun tí ó máa kó ìnira ba yín lágbára lára rẹ̀. Ó ń ṣe àkólékàn (oore ọ̀run) fun yín; aláàánúàti oníkẹ̀ẹ́ ni fún àwọn oní gbàgbọ́ òdodo

[129] Nítorí náà, tí wọ́n bá pẹ̀yìndà, sọ pé: “Allāhu tó fún mi. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni Olúwa Ìtẹ́ ńlá

Yúnùsì

Surah 10

[1] ’Alif Lām Rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà ọgbọ́n

[2] Ṣé ó jẹ́ kàyéfì fún àwọn ènìyàn pé A fi ìmísí ránṣẹ́ sí arákùnrin kan nínú wọn, pé: “Ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí o sì fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní ìró ìdùnnú pé ẹ̀san rere (iṣẹ́ tí wọ́n ṣe) ṣíwájú ti wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.”? Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Dájúdájú òpìdán pọ́nńbélé mà ni (Ànábì) yìí.”

[3] Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Kò sí olùṣìpẹ̀ kan àfi lẹ́yìn ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni

[4] Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí gbogbo yín. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa da á padà (sọ́dọ̀ Rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi déédé san ẹ̀san fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, ohun mímu gbígbóná àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́

[5] (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òòrùn ní ìtànsán. (Ó ṣe) òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀. Ó sì díwọ̀n (ìrísí) rẹ̀ sínú àwọn ibùsọ̀ nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (ọjọ́). Allāhu kò dá ìyẹn bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Ó ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó nímọ̀

[6] Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán àti ohun tí Allāhu dá sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ t’ó ń bẹ̀rù (Allāhu)

[7] Dájúdájú àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run), tí wọ́n yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ dódó sí (ìṣẹ̀mí ayé yìí) àti àwọn afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa

[8] àwọn wọ̀nyẹn, ibùgbé wọn ni Iná nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[9] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi ìgbàgbọ́ òdodo wọn tọ́ wọn sọ́nà. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra

[10] Àdúà wọn nínú rẹ̀ ni “mímọ́ ni fún Ọ, Allāhu”. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni “àlàáfíà”. Ìparí àdúà wọn sì ni pé “gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá”

[11] Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń kánjú mú aburú bá àwọn ènìyàn (nípasẹ̀ èpè ẹnu wọn, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ń) tètè mú oore bá wọn (nípasẹ̀ àdúà), A ìbá ti mú òpin ba ìṣẹ́mí wọn. Nítorí náà, A máa fi àwọn tí kò retí ìpàdé Wa sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà

[12] Nígbà tí ìnira bá kan ènìyàn, ó máa pè Wá lórí ìdùbúlẹ̀ rẹ̀ tàbí ní ìjókòó tàbí ní ìnàró. Nígbà tí A bá mú ìnira rẹ̀ kúrò fún un, ó máa tẹ̀ síwájú (nínú àìgbàgbọ́) bí ẹni pé kò pè Wá sí ìnira tí ó mú un. Báyẹn ni wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn alákọyọ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[13] A kúkú ti pa àwọn ìran kan rẹ́ ṣíwájú yín nígbà tí wọ́n ṣe àbòsí. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Wọn kò sì gbàgbọ́. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san

[14] Lẹ́yìn náà, A ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn nítorí kí Á lè wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe

[15] Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa, t’ó yanjú fún wọn, àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) yóò máa wí pé: “Mú Ƙur’ān kan wá yàtọ̀ sí èyí tàbí kí o yí i padà.” Sọ pé: “Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún mi láti yí i padà láti ọ̀dọ̀ ara mi. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.”

[16] Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni, èmi ìbá tí lè ké al-Ƙur’ān fun yín, àti pé Allāhu ìbá tí fi ìmọ̀ rẹ̀ mọ̀ yín. Mo kúkú ti lo àwọn ọdún kan láààrin yín ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?”

[17] Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí t’ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn ọ̀daràn kò níí jèrè

[18] Wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò lè kó ìnira bá wọn, tí kò sì lè ṣe wọ́n ní àǹfààní lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni olùṣìpẹ̀ wa lọ́dọ̀ Allāhu.” Sọ pé: “Ṣé ẹ máa fún Allāhu ní ìró ohun tí kò mọ̀ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni?” Mímọ́ ni fún Un, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[19] Kí ni àwọn ènìyàn jẹ́ (ní ìpìlẹ̀) bí kò ṣe ìjọ ẹyọ kan (ìjọ ’Islām). Lẹ́yìn náà ni wọ́n yapa ẹnu. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan t’ó ti ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, Àwa ìbá ti yanjú ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí láààrin ara wọn

[20] Wọ́n ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí àmì kan sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Nítorí náà, sọ pé: “Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”

[21] Nígbà tí A bá fún àwọn ènìyàn ní ìdẹ̀ra kan tọ́wò lẹ́yìn tí ìnira ti fọwọ́ bà wọ́n, nígbà náà ni wọ́n máa dète sí àwọn āyah Wa. Sọ pé: “Allāhu yára jùlọ níbi ète. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń dá léte.”

[22] (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó mu yín rìn lórí ilẹ̀ àti ní ojú omi, títí di ìgbà tí ẹ bá wà nínú ọkọ̀ ojú-omi, tí atẹ́gùn t’ó dára sì ń tukọ̀ wọn lọ, inú wọn yó sì máa dùn sí i. (Àmọ́) atẹ́gùn líle kọ lù ú, ìgbì omi dé bá wọn ní gbogbo àyè, wọ́n sì lérò pé dájúdájú wọ́n ti fi (àdánwò) yí àwọn po, wọ́n sì pe Allāhu pẹ̀lú ṣíṣe àfọ̀mọ́-àdúà fún Un pé: “Dájúdájú tí O bá fi lè gbà wá là níbi èyí, dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”

[23] Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó gbà wọ́n là tán ìgbà náà ni wọ́n tún ń ṣe ìbàjẹ́ kiri lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ìbàjẹ́ yín ń bẹ lórí yín. (Ìbàjẹ́ yín sì jẹ́) ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí yín. A sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[24] Àpèjúwe ìṣẹ̀mí ayé dà bí omi kan tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí àwọn irúgbìn nínú ohun tí ènìyàn àti àwọn ẹran-ọ̀sìn ń jẹ sì gbà á sára, títí di ìgbà tí ilẹ̀ yóò fi lọ́ràá. Ó sì mú ọ̀ṣọ́ (ara) rẹ̀ jáde. Àwọn t’ó ni í sì lérò pé àwọn ni alágbára lórí rẹ̀, (nígbà náà ni) àṣẹ Wa dé bá a ní òru tàbí ní ọ̀sán. A sì sọ ọ́ di oko tí wọ́n fà tu dànù bí ẹni pé kò sí níbẹ̀ rárá rí ní àná. Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ aláròjinlẹ̀

[25] Allāhu ń pèpè sí ilé Àlàáfíà. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām)

[26] Rere àti àlékún (oore) wà fún àwọn t’ó ṣe rere. Eruku tàbí ìyẹpẹrẹ kan kò níí bò wọ́n lójú mọ́lẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[27] Àwọn t’ó sì ṣ’iṣẹ́ aburú, ẹ̀san aburú bí irú rẹ̀ (ni ẹ̀san wọn). Ìyẹpẹrẹ sì máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Kò sí aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu. (Wọ́n máa dà bí) ẹni pé wọ́n fi apá kan òru t’ó ṣókùnkùn bò wọ́n lójú pa. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[28] Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn t’ó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pé: “Ẹ dúró pa sí àyè yín, ẹ̀yin àti àwọn òrìṣà yín.” Nítorí náà, A yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn òrìṣà wọn sì wí pé: “Àwa kọ́ ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún

[29] Nítorí náà, Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin àwa àti ẹ̀yin pé àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa ìjọ́sìn yín (tí ẹ̀ ṣe fún wa).”

[30] Níbẹ̀ yẹn, ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan máa dá ohun t’ó ṣe síwájú mọ̀. Wọn yó sì da wọ́n padà sọ́dọ̀ Allāhu, Olúwa wọn, Òdodo. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ sì máa dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́

[31] Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?” Wọn yóò wí pé: "Allāhu" Nígbà náà, sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni

[32] Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Òdodo. Kí sì ni ó ń bẹ lẹ́yìn Òdodo bí kò ṣe ìṣìnà? Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo

[33] Báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe wá sí ìmúṣẹ lórí àwọn t’ó ṣèbàjẹ́ pé dájúdájú wọn kò níí gbàgbọ́

[34] Sọ pé: "Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè pilẹ̀ dídá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú)?" Sọ pé: "Allāhu l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú). Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo

[35] Sọ pé: "Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni t’ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo?" Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo. Nígbà náà, ṣé Ẹni t’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo l’ó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí pé kí wọ́n máa tẹ̀lé ni tàbí ẹni tí kò lè dá ọ̀nà mọ̀ fúnra rẹ̀ àfi tí A bá fi mọ̀nà?” Nítorí náà, kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí

[36] Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò sì rí kiní kan tẹ̀lé bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àròsọ kò sì lè rọrọ̀ kiní kan níwájú òdodo. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[37] Al-Ƙur’ān yìí kì í ṣe n̄ǹkan tí ó ṣe é dáhun (láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn) lẹ́yìn Allāhu, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣe àlàyé (àwọn) Tírà náà. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. (Ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[38] Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni? Sọ pé: "Ẹ mú sūrah kan bí irú rẹ̀ wá. Kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè pè lẹ́yìn Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[39] Kò rí bẹ́è, wọ́n pe ohun tí wọn kò ní ìmọ̀ rẹ̀ nírọ́ ni. Àti pé ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò tí ì dé bá wọn (ni wọ́n fi pè é nírọ́). Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) nírọ́. Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ṣe rí

[40] Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó gbà á gbọ́ ní òdodo. Ó tún ń bẹ́ nínú wọn ẹni tí kò gbà á gbọ́. Olúwa rẹ sì ni Onímọ̀-jùlọ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́

[41] Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ pé: “Tèmi ni iṣẹ́ mi. Tiyín ni iṣẹ́ yín. Ẹ̀yin yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí mò ń ṣe níṣẹ́. Èmi náà sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

[42] Ó sì wà nínú wọn, àwọn t’ó ń tẹ́tí sí ọ. Ṣé ìwọ l’o máa mú adití gbọ́rọ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe làákàyè

[43] Ó tún ń bẹ nínú wọn ẹni t’ó ń wò ọ́. Ṣé ìwọ l’o máa fi afọ́jú mọ̀nà ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ríran

[44] Dájúdájú Allāhu kò níí fí kiní kan ṣàbòsí sí ènìyàn. Ṣùgbọ́n ènìyàn ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn

[45] Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó wọn jọ àfi bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé ju àkókò kan nínú ọ̀sán. Wọn yó sì dára wọn mọ̀. Dájúdájú àwọn t’ó pe ìpàdé Allāhu nírọ́ ti ṣòfò; wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà

[46] Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, Allāhu ni Arínú-róde ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[47] Òjíṣẹ́ ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, nígbà tí Òjíṣẹ́ wọn bá dé, A óò ṣèdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[48] Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

[49] Sọ pé: “Èmi kò ní ìkápá ìnira tàbí oore kan fún ẹ̀mí ara mi àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Gbèdéke àkókò ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú di àkókò kan, wọn kò sì níí fà á sẹ́yìn.”

[50] Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Rẹ̀ bá dé ba yín ní òru tàbí ní ọ̀sán? Èwo nínú rẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú?”

[51] Ṣé lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán ni ẹ máa gbà á gbọ́? Ṣé nísinsìn yìí (ni ẹ óò gbà á gbọ́), tí ẹ sì kúkú ti ń wá a pẹ̀lú ìkánjú

[52] Lẹ́yìn náà, A óò sọ fún àwọn t’ó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà gbére wò.” Ṣé A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[53] Wọ́n sì ń bèèrè fún ìró rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “ṣé òdodo ni?” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Mo fi Olúwa mi búra. Dájúdájú òdodo ni. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.”

[54] Àti pé tí ó bá jẹ́ pé gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ jẹ́ ti ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan t’ó ṣàbòsí, ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi ìyà). Wọn yóò fi igbe àbámọ̀ pamọ́ nígbà tí wọ́n bá rí Ìyà. A ó ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[55] Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Gbọ́! Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò nímọ̀

[56] Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí

[57] Èyin ènìyàn, ìṣítí kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ti dé ba yín. Ìwòsàn ni fún n̄ǹkan t’ó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[58] Sọ pé: “Pẹ̀lú àjùlọ oore Allāhu (ìyẹn, al-Ƙur’ān) àti àánú Rẹ̀ (ìyẹn, ’Islām), nítorí ìyẹn ni kí wọ́n máa fi dunnú; ó sì lóore jùlọ sí ohun tí àwọn (aláìgbàgbọ́) ń kó jọ (nínú oore ayé).”

[59] Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fun yín nínú arísìkí, tí ẹ̀yin fúnra yín ṣe àwọn kan ní èèwọ̀ àti ẹ̀tọ́. Ṣé Allāhu l’Ó yọ̀ǹda fun yín ni tàbí ẹ̀ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?”

[60] Kí ni èrò-ọkàn àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde ná? Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kì í dúpẹ́ (fún Un)

[61] Ìwọ kò níí wà nínú ìṣe kan, ìwọ kò sì níí ké (āyah kan) nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀yin kò níí ṣe iṣẹ́ kan àfi kí Àwa jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe é. Kiní kan kò pamọ́ fún Olúwa rẹ; tí ó mọ ní òdiwọ̀n iná-igún nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀, kí ó tún kéré jú ìyẹn lọ tàbí kí ó tóbi jù ú lọ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú

[62] Gbọ́, dájúdájú àwọn ọ̀rẹ́ Allāhu, kò níí sí ìbẹ̀rù (ìyà ọ̀run) fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́ (lórí oore ayé)

[63] (Àwọn ni) àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù (Allāhu)

[64] Ti wọn ni ìró ìdùnnú nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kò sí ìyípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu. Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá

[65] Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú gbogbo agbára pátápátá ń jẹ́ ti Allāhu. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[66] Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ẹnikẹ́ni t’ó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ẹnikẹ́ni t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀. Kí ni àwọn t’ó ń pe àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu ń tẹ̀lé ná? Wọn kò tẹ̀lé (kiní kan) bí kò ṣe àròsọ. Wọn kò sì ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́

[67] Òun ni Ẹni t’Ó ṣe òru fun yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó ṣe) ọ̀sán ní (àsìkò) tí ẹ óò ríran (kedere). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀ (òdodo)

[68] Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹ̀dá di ọmọ.” - Mímọ́ ni fún Un. Òun ní Olùrọrọ̀. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. – Kò sí ẹ̀rí kan lọ́dọ̀ yín fún èyí. Ṣé ẹ fẹ́ ṣàfitì ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni

[69] Sọ pé: “Dájúdájú àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.”

[70] Ìgbádùn bín-íntín (lè wà fún wọn) nílé ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, A óò fún wọn ní ìyà líle tọ́ wò nítorí pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́

[71] Ka ìròyìn (Ànábì) Nūh fún wọn. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó bá jẹ́ pé ìdúró mi (pẹ̀lú yín) àti bí mo ṣe ń fi àwọn āyah Allāhu ṣe ìṣítí fun yín bá lágbara lára yín, nígbà náà Allāhu ni mo gbáralé. Nítorí náà, ẹ pa ìmọ̀ràn yín pọ̀, (kí ẹ sì ké pe) àwọn òrìṣà yín. Lẹ́yìn náà, kí ìpinnu ọ̀rọ̀ yín má ṣe wà ní bòńkẹ́lẹ́ láààrin yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ yanjú ọ̀rọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára mọ́

[72] Tí ẹ bá sì kọ̀yìn (sí ìrántí), èmi kò kúkú tọrọ owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín. Kò sí ẹ̀san kan fún mi (níbì kan) bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì ti pa mí láṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn mùsùlùmí.”

[73] Nígbà náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, A gbà á là, òun àti àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omí. A sì ṣe wọ́n ní àrólé (lórí ilẹ̀). A sì tẹ àwọn t’ó pe āyah Wa nírọ́ rì sínú agbami. Nítorí náà, wo bí ìkángun àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ṣe rí

[74] Lẹ́yìn náà, A gbé àwọn Òjíṣẹ́ kan dìde sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Àwọn náà kò kúkú gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ Ànábì Nūh) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn, ìyẹn ni pé, irú kan-ùn ni wọ́n). Báyẹn ni A ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn alákọyọ

[75] Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn wọn A fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā àti Hārūn níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n ṣègbéraga. Wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀

[76] Nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Dájúdájú èyí ni idán pọ́nńbélé.”

[77] (Ànábì) Mūsā sọ pé: "Ṣé n̄ǹkan tí ẹ̀yin yóò máa wí nípa òdodo ni pé idán ni nígbà tí ó dé ba yín? Ṣé idán sì ni èyí bí? Àwọn òpìdán kò sì níí jèrè

[78] Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè ṣẹ́rí wa kúrò níbi ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ (nínú ìbọ̀rìṣà) àti nítorí kí títóbi sì lè jẹ́ tẹ̀yin méjèèjì lórí ilẹ̀? Àwa kò sì níí gba ẹ̀yin méjèèjì gbọ́.”

[79] Fir‘aon wí pé: “Ẹ lọ mú gbogbo àwọn onímọ̀ nípa idán pípa wá fún mi.”

[80] Nígbà tí àwọn òpìdán sì dé, (Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ máa jù sílẹ̀.”

[81] Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Idán ni ohun tí ẹ mú wá. Dájúdájú Allāhu sì máa bà á jẹ́. Dájúdájú Allāhu kò sì níí ṣàtúnṣe iṣẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́

[82] Allāhu sì máa mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ìbáà kórira rẹ̀

[83] Nítorí náà, kò sí ẹni t’ó gba (Ànábì) Mūsā gbọ́ àfi àwọn àrọ́mọdọ́mọ kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù-bojo (wọn) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè wọn pé ó máa fòòró àwọn. Dájúdájú Fir‘aon kúkú ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Àti pé, dájúdájú ó wà nínú àwọn alákọyọ

[84] (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ẹ bá jẹ́ ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun náà ni kí ẹ gbáralé tí ẹ bá jẹ́ mùsùlùmí.”

[85] Nítorí náà, wọ́n sọ pé: "Allāhu la gbáralé. Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún ìjọ alábòsí

[86] Kí Ó sì fi àánú Rẹ gbà wá là lọ́wọ́ ìjọ aláìgbàgbọ́

[87] A sì ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā àti arákùnrin rẹ̀ pé: “Kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn ibùgbé fún àwọn ènìyàn yín sí ìlú Misrọ. Kí ẹ sì sọ ibùgbé yín di ibùkírun. Kí ẹ sì máa kírun. Àti pé, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.”

[88] (Ànábì) Mūsā sọ pé: "Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O fún Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ àti dúkìá nínú ìṣẹ̀mí ayé. Olúwa wa, (O fún wọn) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ. Olúwa wa, pa dúkìá wọn rẹ́, kí O sì mú ọkàn wọn le, kí wọ́n má gbàgbọ́ mọ́ títí wọn fi máa rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[89] (Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú Mo ti gba àdúà ẹ̀yin méjèèjì. Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì dúró ṣinṣin. Ẹ má ṣe tẹ̀lé ojú ọ̀nà àwọn tí kò nímọ̀

[90] A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl la agbami odò já. Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, ní ti àbòsí àti ìtayọ ẹnu-àlà, títí ìtẹ̀rì sínú agbami òkun fi bá a. Ó sì wí pé: “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́. Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.”

[91] Ṣé nísinsìn yìí, tí ìwọ ti yapa ṣíwájú, tí o sì wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́

[92] Nítorí náà, ní òní ní A óò gbé òkú rẹ jáde sí orí ilẹ̀ téńté nítorí kí o lè jẹ́ àmì (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa

[93] A kúkú ṣe ibùgbé fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ibùgbé alápọ̀n-ọ́nlé. A sì pèsè fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Nígbà náà, wọn kò yapa ẹnu (sí ’Islām) títí ìmọ̀ fi dé bá wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí

[94] Tí o bá wà nínú iyèméjì nípa n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (pé orúkọ rẹ àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ wà nínú Taorāt àti ’Injīl), bi àwọn t’ó ń ka Tírà ṣíwájú rẹ léèrè wò. Dájúdájú òdodo ti dé bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì

[95] O ò gbọdọ̀ wà lára àwọn t’ó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, nítorí kí o má baà wà lára àwọn ẹni òfò

[96] Dájúdájú àwọn tí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ti kò lé lórí, wọn kò níí gbàgbọ́

[97] gbogbo āyah ìbáà dé bá wọn, títí wọ́n máa fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[98] Kò kúkú sí ìlú kàn, t’ó gbàgbọ́ (lásìkò ìyà), tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì ṣe é ní àǹfààní àfi ìjọ (Ànábì) Yūnus. Nígbà tí wọ́n gbàgbọ́, A mú àbùkù ìyà kúrò fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé. A sì jẹ́ kí wọ́n jẹ ìgbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀

[99] Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ìbá gbàgbọ́, gbogbo wọn pátápátá. Nítorí náà, ṣé ìwọ l’o máa jẹ wọ́n nípá ni títí wọn yóò fi di onígbàgbọ́ òdodo

[100] Ẹ̀mí kan kò lè gbàgbọ́ àfi pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Ó sì máa fi ìyà jẹ àwọn tí kò ṣe làákàyè

[101] Sọ pé: "Ẹ wòye sí n̄ǹkan tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn āyah àti ìkìlọ̀ kò sì níí rọ ìjọ aláìgbàgbọ́ lọ́rọ̀

[102] Nítorí náà, ṣé wọ́n tún ń retí (n̄ǹkan mìíràn) ni bí kò ṣe (ìparun) irú ti ìgbà àwọn t’ó ré kọjá lọ ṣíwájú wọn. Sọ pé: “Ẹ máa retí nígbà náà. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”

[103] Lẹ́yìn náà, A óò gba àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn t’ó gbàgbọ́ là. Báyẹn ní ó ṣe jẹ́ ojúṣe Wa láti gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là

[104] Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ẹ̀sìn mi. Nígbà náà, èmi kò níí jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣùgbọ́n èmi yóò máa jọ́sìn fún Allāhu, Ẹni tí Ó máa gba ẹ̀mí yín. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[105] (Wọ́n tún pa mí láṣẹ pé): “Dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ

[106] Àti pé má ṣe pè lẹ́yìn Allāhu n̄ǹkan tí kò lè ṣe ọ́ ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá ọ. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà, dájúdájú ìwọ ti wà nínú àwọn alábòsí.”

[107] Tí Allāhu bá mú ìnira bá ọ, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun. Tí Ó bá sì gbèrò oore kan pẹ̀lú rẹ, kò sí ẹni tí ó lè dá oore Rẹ̀ padà. Ó ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[108] Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú òdodo ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Èmi sì kọ́ ni olùṣọ́ fun yín

[109] Tẹ̀lé ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí. Kí o sì ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́. Òun sì lóore julọ nínú àwọn olùdájọ́

Húdù

Surah 11

[1] ’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán

[2] (A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Allāhu. Dájúdájú emi ni olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[3] (A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé kí ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó máa fun yín ní ìgbádùn dáadáa títí di gbèdéke àkókò kan. Ó máa fún oníṣẹ́-àṣegbọrẹ ní ẹ̀san iṣẹ́ àṣegbọrẹ rẹ̀. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá fun yín

[4] Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí yín. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[5] Gbọ́, dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bo ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà wọn láti lè fara pamọ́ fún Allāhu. Kíyè sí i, nígbà tí wọ́n ń yíṣọ wọn bora, Allāhu mọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi pamọ́ àti n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[6] Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan t’ó wà lórí ilẹ̀ àfi kí arísìkí rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì mọ ibùgbé rẹ̀ (nílé ayé) àti ilẹ̀ tí ó máa kú sí. Gbogbo rẹ̀ ti wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú

[7] Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà - Ìtẹ́ ọlá Rẹ̀ sì wà lórí omi (ṣíwájú èyí) – nítorí kí Ó lè dan yín wò pé, èwo nínú yín l’ó dára jùlọ (níbi) iṣẹ́ rere. Tí o bá kúkú sọ pé dájúdájú wọn yóò gbe yín dìde lẹ́yìn ikú, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”

[8] Dájúdájú tí A bá sún ìyà ṣíwájú fún wọn di ìgbà t’ó ní òǹkà, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Kí l’ó ń dá a dúró ná?” Gbọ́, ní ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, kò níí ṣe é gbé kúrò fún wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà t’ó máa yí wọn po

[9] Àti pé dájúdájú tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò láti ọ̀dọ̀ Wa, lẹ́yìn náà, tí A bá gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, dájúdájú ó máa di olùsọ̀rètínù, aláìmoore

[10] Dájúdájú tí A bá sì fún un ní ìdẹ̀ra tọ́wò lẹ́yìn ìnira t’ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: “Àwọn aburú ti kúrò lọ́dọ̀ mi.” Dájúdájú ó máa di aláyọ̀pọ̀rọ́, onífáàrí

[11] Àyàfi àwọn t’ó bá ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn, ti wọn ni àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi

[12] Bóyá o fẹ́ gbé apá kan ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ sílẹ̀, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọkàn rẹ nípa rẹ̀ (ní ti ìpáyà pé) wọ́n ń wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí àpótí-ọrọ̀ kan sọ̀kalẹ̀ fún un, tàbí kí mọlāika kan bá a wá?” Olùkìlọ̀ ni ìwọ. Allāhu sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan

[13] Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni.” Sọ pé: “Ẹ mú sūrah mẹ́wàá àdáhun bí irú rẹ̀ wá, kí ẹ sì ké sí ẹni tí ẹ bá lè ké sí lẹ́yìn Allāhu tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

[14] Nígbà náà tí wọn kò bá da yín lóhùn, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Allāhu. Àti pé kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin yóò di mùsùlùmí

[15] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé

[16] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé sì máa bàjẹ́. Òfò sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[17] Ǹjẹ́ ẹni t’ó ń bẹ́ lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (ìyẹn, Ànábì s.a.w.), tí olùjẹ́rìí kan (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) sì ń ké al-Ƙur’ān (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn), (ǹjẹ́ Ànábì yìí jọ olùṣìnà bí?) Àwọn (mùsùlùmí) wọ̀nyí ni wọ́n sì gbà á gbọ́ ní òdodo. Ẹnikẹ́ni t’ó bá ṣàì gbà á gbọ́ nínú àwọn ìjọ (nasara, yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ), nígbà náà Iná ni àdéhùn rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa al-Ƙur’ān. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́

[18] Àti pé ta ni ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu? Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n yóò kó wá síwájú Olúwa wọn. Àwọn ẹlẹ́rìí (ìyẹn, àwọn mọlāika) yó sì máa sọ pé: "Àwọn wọ̀nyí ni àwọn t’ó parọ́ mọ́ Olúwa wọn." Gbọ́, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn alábòsí

[19] àwọn t’ó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[20] Àwọn wọ̀nyẹn kò lè mórí bọ́ nínú ìyà Allāhu lórí ilẹ̀ àti pé kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu. A ó sì ṣe àdìpèlé ìyà fún wọn. Wọn kò lè gbọ́. Àti pé wọn kì í ríran (rí òdodo)

[21] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́

[22] Ní ti òdodo, dájúdájú àwọn gan-an ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[23] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sì dúnní mọ́ ìronúpìwàdà sọ́dọ̀ Olúwa wọn, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[24] Àfiwé ìjọ méjèèjì dà bí afọ́jú àti adití pẹ̀lú olùríran àti olùgbọ́rọ̀. Ǹjẹ́ àwọn méjèèjì dọ́gba ní àfiwé bí? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni

[25] A sì kúkú ti rán (Ànábì) Nūh sí ìjọ rẹ̀ (láti sọ pé) dájúdájú olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni mo jẹ́ fun yín

[26] (Mò ń kìlọ̀) pé kí ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ẹlẹ́ta-eléro fun yín

[27] Àwọn aṣíwájú t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ sì wí pé: "Àwa kò mọ̀ ọ́ sí ẹnì kan tayọ abara bí irú wa. Àwa kò sì mọ àwọn t’ó tẹ̀lé ọ sí ẹnì kan kan tayọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ nínú wa, ọlọ́pọlọ bín-íntín. Àti pé àwa kò ri yín sí ẹni t’ó fi ọ̀nà kan kan ní àjùlọ lórí wa, ṣùgbọ́n a kà yín kún òpùrọ́

[28] (Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí mo bá wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí Ó sì fún mi ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí wọn kò sí jẹ́ kí ẹ ríran rí (òdodo náà), ǹjẹ́ a óò fi dandan mu yín bí, nígbà tí ẹ̀mí yín kọ̀ ọ́

[29] Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì níí le àwọn t’ó gbàgbọ́ dànù. Dájúdájú wọn yóò pàdé Olúwa wọn, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ń ri yín sí ìjọ aláìmọ̀kan

[30] Ẹ̀yin ìjọ mi, ta ni ó máa ràn mí lọ́wọ́ níbi (ìyà) Allāhu tí mo bá lé wọn dànù? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni

[31] Èmi kò sì sọ fun yín pé àwọn ilé-owó Allāhu ń bẹ lọ́dọ̀ mi. Èmi kò sì mọ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ pé mọlāika ni mí. Èmi kò sì lè sọ fún àwọn tí ẹ̀ ń fojú bín-íntín wò pé, Allāhu kò níí ṣoore fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa n̄ǹkan t’ó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, dájúdájú mo ti wà nínú àwọn alábòsí

[32] Wọ́n wí pé: "Ìwọ Nūh, O mà kúkú ti jà wá níyàn. O sì ṣe àríyànjiyàn púpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa wá tí o bá wà lára àwọn olódodo

[33] (Ànábì Nūh) sọ pé: "Allāhu l’Ó máa mú un wá ba yín tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́

[34] Ìmọ̀ràn mi kò sì lè ṣe yín ní àǹfààní tí mo bá fẹ́ gbà yín nìmọ̀ràn, tí Allāhu bá fẹ́ pa yín run. Òun ni Olúwa yín. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí

[35] Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni." Sọ pé: "Tí mó bá hun ún, èmi ni mo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń dá lẹ́ṣẹ̀

[36] A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh pé dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa gbàgbọ́ mọ́ nínú ìjọ rẹ àfi ẹni t’ó ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[37] Kí o sì kan ọkọ̀ ojú-omi náà lójú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Má sì ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó ṣàbòsí. Dájúdájú A máa tẹ̀ wọ́n rì ni

[38] Ó sì ń kan ọkọ̀ ojú-omi náà lọ. Nígbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Ànábì Nūh) sì sọ pé: "Tí ẹ bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, dájúdájú àwa náà yóò fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́

[39] Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí

[40] (Báyìí ni ọ̀rọ̀ wà) títí di ìgbà tí àṣẹ Wa dé, omi sì ṣẹ́yọ gbùú láti ojú-àrò (tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì). A sọ pé: "Kó gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ sínú ọkọ̀ ojú-omi - àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí (fún ìparun) - àti ẹnikẹ́ni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì sí ẹni t’ó ní ìgbàgbọ́ òdodo pẹ̀lú rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀

[41] (Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ wọ inú ọkọ̀ ojú-omi náà. Ó máa rìn, ó sì máa gúnlẹ̀ ní orúkọ Allāhu. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[42] Ó sì ń gbé wọn lọ nínú ìgbì omi t’ó dà bí àpáta. (Ànábì Nūh) sì ké sí ọmọkùnrin rẹ̀, tí ó ti yara rẹ̀ sọ́tọ̀: "Ọmọkùnrin mi, gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú wa. Má sì ṣe wà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́

[43] Ó wí pé: “Èmi yóò forí pamọ́ síbi àpáta kan tí ó máa là mí níbi omi.” (Ànábì Nūh) sọ pé: "Kò sí aláàbò kan ní òní níbi àṣẹ Allāhu àfi ẹni tí Allāhu bá ṣàánú." Ìgbì omi sì la àwọn méjèèjì láààrin. Ó sì di ara àwọn olùtẹ̀rì sínú omi

[44] A sọ pé: "Ilẹ̀, fa omi rẹ mu. Sánmọ̀, dáwọ́ (òjò) dúró." Wọ́n sì dín omi kù. Ọ̀rọ̀ ìparun wọn sì wá sí ìmúṣẹ. (Ọkọ̀ ojú-omi) sì gúnlẹ̀ sórí àpáta Jūdī. A sì sọ pé: “Ìjìnnà réré sí ìkẹ́ Allāhu ni ti ìjọ alábòsí.”

[45] (Ànábì) Nūh pe Olúwa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú ọmọ mi wà nínú ará ilé mi. Àti pé dájúdájú àdéhùn Rẹ, òdodo ni. Ìwọ l’O sì mọ ẹjọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́

[46] Allāhu sọ pé: “Nūh, dájúdájú kò sí nínú ará ilé rẹ (ní ti ẹ̀sìn). Dájúdájú iṣẹ́ tí kò dára ni. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ bi Mí léèrè n̄ǹkan tí o ò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú Èmi ń kìlọ̀ fún ọ nítorí kí o má baà di ara àwọn aláìmọ̀kan.”

[47] Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń sá di Ọ́ níbi kí n̄g bi Ọ́ léèrè n̄ǹkan tí èmi kò ní ìmọ̀ rẹ̀. Tí O ò bá foríjìn mí, kí O sì ṣàánú mi, èmi yóò wà lára àwọn ẹni òfò

[48] A sọ pé: "Nūh, sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Wa. Àti pé kí ìbùkún wà pẹ̀lú rẹ àti àwọn ìjọ nínú àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ. Àwọn ìjọ kan (tún ń bọ̀), tí A óò fún wọn ní ìgbádùn (oore ayé). Lẹ́yìn náà, ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ bà wọ́n láti ọ̀dọ̀ Wa

[49] Ìwọ̀nyí wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi (ìmísí rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ àti ìjọ rẹ kò nímọ̀ rẹ̀ ṣíwájú èyí (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ). Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú ìkángun rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[50] (Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran ‘Ād ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe aládàápa irọ́

[51] Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá mi. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni

[52] Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olùwa Ẹlẹ́dàá yín, lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè rọ̀jò fun yín ní púpọ̀ láti sánmọ̀ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún agbára kún agbára yín. Ẹ má ṣe pẹ̀yìn dà láti di ẹlẹ́ṣẹ̀ (sínú àìgbàgbọ́)

[53] Wọ́n wí pé: "Hūd, o ò mú ẹ̀rí kan t’ó yanjú wá fún wa. Àwa kò sì níí gbé àwọn òrìṣà wa jù sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ. Àti pé àwa kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ

[54] ǹkan tí à ń sọ fún ọ ni pé àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi ìnira kàn ọ́ (l’ó fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn)." Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ

[55] dípò jíjọ́sìn fún Allāhu. Nítorí náà, ẹ parapọ̀ déte sí mi. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má ṣe lọ́ mi lára

[56] Dájúdájú èmi gbáralé Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Kò sí ẹ̀dá kan àfi kí (ó jẹ́ pé) Òun l’Ó máa fi àásó orí rẹ̀ mú un. Dájúdájú Olúwa mi wà lórí ọ̀nà tààrà

[57] Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fun yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan t’ó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ ò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan

[58] Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà t’ó nípọn

[59] Ìran ‘Ād nìyẹn; wọ́n tako àwọn āyah Olúwa wọn. Wọ́n sì yapa àwọn Òjíṣẹ́ wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé àṣẹ gbogbo àwọn aláfojúdi alátakò-òdodo

[60] A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́, dájúdájú ìran ‘Ād ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, ìjìnnà réré sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìran ‘Ād, ìjọ (Ànábì) Hūd

[61] (Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Thamūd ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Òun l’Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá yín láti ara (erùpẹ̀) ilẹ̀. Ó sì fun yín ní ìṣẹ̀mí lò lórí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùsúnmọ́, Olùjẹ́pè (ẹ̀dá).”

[62] Wọ́n wí pé: “Sọ̄lih, o ti wà láààrin wa ní ẹni tí a ní ìrètí sí (pé o máa sanjọ́) ṣíwájú (ọ̀rọ̀ tí o sọ) yìí. Ṣé o máa kọ̀ fún wa láti jọ́sìn fún ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún ni? Dájúdájú àwa mà wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wá sí.”

[63] Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé èmi wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí ìkẹ́ kan sì dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ta ni ẹni tí ó máa ràn mí lọ́wọ́ nínú (ìyà) Allāhu tí mo bá yapa Rẹ̀? Kò sí kiní kan tí ẹ lè fi ṣe àlékún rẹ̀ fún mi yàtọ̀ sí ìparun

[64] Ẹ̀yin ìjọ mi, èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. Ó jẹ́ àmì fun yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ́ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ìnira kàn án nítorí kí ìyà t’ó súnmọ́ má báa jẹ yín

[65] Wọ́n sì gún un pa. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ̀gbádùn nínú ilé yín fún ọjọ́ mẹ́ta (kí ìyà yín tó dé). Ìyẹn ni àdéhùn tí kì í ṣe irọ́.”

[66] Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Sọ̄lih àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. (A tún gbà wọ́n là) nínú àbùkù ọjọ́ yẹn. Dájúdájú Olúwa Rẹ, Òun ni Alágbára, Olùborí (ẹ̀dá)

[67] Ohùn igbe líle gbá àwọn t’ó ṣàbòsí mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn

[68] Àfi bí ẹni pé wọn kò gbénú ìlú náà rí. Gbọ́, dájúdájú ìran Thamūd ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, ìjìnnà réré sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìjọ Thamūd

[69] Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ti mú ìró ìdùnnú wá bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Wọ́n sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Ó sọ pé: “Àlàáfíà (fun yín).” Kò sì pẹ́ rárá t’ó fi gbé ọmọ màálù àyangbẹ wá

[70] Nígbà tí ó rí ọwọ́ wọn pé kò kan oúnjẹ, ó f’ojú òdì wo (àìjẹun) wọn. Ìbẹ̀rù wọn sí wà nínú ọkàn rẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwọn ènìyàn (Ànábì) Lūt ni Wọ́n rán àwa sí.”

[71] Ìyàwó rẹ̀ wà ní ìdúró, ó rẹ́rìn-ín. A sì fún un ní ìró ìdùnnú (pé ó máa bí) ’Ishāƙ. Àti pé lẹ́yìn ’Ishāƙ ni Ya‘ƙūb (ìyẹn, ọmọọmọ)

[72] Ó sọ pé: “Hẹ̀n-ẹ́n! Ṣé pé mo máa bímọ? Arúgbóbìnrin ni mi, baálé mi yìí sì ti dàgbàlágbà! Dájúdájú èyí ni n̄ǹkan ìyanu.”

[73] Wọ́n sọ pé: “Ṣé o máa ṣèèmọ̀ nípa àṣẹ Allāhu ni? Ìkẹ́ Allāhu àti ìbùkún Rẹ̀ kí ó máa bẹ fun yín, ẹ̀yin ará ilé (yìí). Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́pẹ́, Ẹlẹ́yìn.”

[74] Nígbà tí ìbẹ̀rù kúrò lára (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, tí ìró ìdùnnú sì ti dé bá a, ó sì ń pàrọwà fún (àwọn Òjíṣẹ́) Wa nípa ìjọ (Ànábì) Lūt

[75] Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni aláfaradà, olùrawọ́rasẹ̀, olùronúpìwàdà

[76] (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Dájúdájú àṣẹ Olúwa rẹ ti dé. Àti pé dájúdájú àwọn ni ìyà tí kò ṣe é dá padà yóò dé bá

[77] Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé bá (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó sì sọ pé: “Èyí ni ọjọ́ t’ó le púpọ̀.”

[78] Àwọn ènìyàn rẹ̀ wá bá a, tí wọ́n ń sáré gbọ̀n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ti ń ṣe iṣẹ́ aburú (bíi ìbálòpọ̀ láààrin ọkùnrin àti ọkùnrin). Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn wọ̀nyẹn ni ọmọbìnrin mi, wọ́n mọ́ jùlọ fun yín (láti fi ṣaya). Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe dójú tì mí lọ́dọ̀ àlejò mi. Ṣé kò sí ọkùnrin olùmọ̀nà kan nínú yín ni

[79] Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú ti mọ̀ pé àwa kò lẹ́tọ̀ọ́ kan sí àwọn ọmọbìnrin rẹ. O sì ti mọ n̄ǹkan tí à ń fẹ́.”

[80] Ó sọ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú agbára kan wà fún mi lórí yín ni, tàbí (pé) mo lè darapọ̀ mọ́ ẹbí kan t’ó lágbára ni, (èmi ìbá di yín lọ́wọ́ níbi aburú yín)

[81] (Àwọn mọlāika) sọ pé: “(Ànábì) Lūt, dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa. Wọn kò lè (fọwọ́ aburú) kàn ọ́. Nítorí náà, mú àwọn ará ilé rẹ jáde ní abala kan nínú òru. Kí ẹnì kan nínú yín má sì ṣe ṣíjú wẹ̀yìn wò, àfi ìyàwó rẹ, dájúdájú àdánwò rẹ̀ ni ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Dájúdájú àkókò (àdánwò) wọn ni òwúrọ̀. Ṣé òwúrọ̀ kò súnmọ́ ni

[82] Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n sì dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí ní tẹ̀léǹtẹ̀lé

[83] (Àwọn òkúta náà) ti ní àmì (orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lára) láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Wọn kò sì jìnnà sí àwọn alábòsí

[84] (Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Mọdyan ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣua‘eb. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ má ṣe dín kóńgò àti òṣùwọ̀n kù. Mo rí yín pẹ̀lú dáadáa (tí Allāhu ṣe fun yín). Dájúdájú èmi sì ń páyà ìyà ọjọ́ kan tí ó máa yi yín po

[85] Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gbadọ́gba. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe balẹ̀ jẹ́ ní ti òbìlẹ̀jẹ́

[86] Ohun tí Allāhu bá ṣẹ́kù fun yín (nínú halāl) lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Èmi kì í sì ṣe olùṣọ́ lórí yín

[87] Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, ṣé ìrun rẹ l’ó ń pa ọ́ láṣẹ pé kí á gbé ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún jù sílẹ̀, tàbí (ìrun rẹ ló ń kọ̀ fún wa) láti ṣe ohun tí a bá fẹ́ nínú dúkìá wa? Dájúdájú ìwọ mà ni aláfaradà, olùmọ̀nà (lójú ara rẹ nìyẹn)

[88] Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé mo wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí (Olúwa mi) sì fún mi ní arísìkí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní arísìkí t’ó dára (ṣé kí n̄g máa jẹ harāmu pẹ̀lú rẹ̀ ni?). Èmi kò sì fẹ́ yapa yín nípa n̄ǹkan tí mò ń kọ̀ fun yín (ìyẹn ni pé, èmi náà ń lo ohun tí mò ń sọ fun yín). Kò sí ohun tí mo fẹ́ bí kò ṣe àtúnṣe pẹ̀lú bí mo ṣe lágbára mọ. Kò sí kòǹgẹ́ ìmọ̀nà kan fún mi bí kò ṣe pẹ̀lú (ìyọ̀ǹda) Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí sí (fún ìronúpìwàdà)

[89] Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí (bí) ẹ ṣe ń yapa mi mu yín lùgbàdì irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọ (Ànábì) Nūh tàbí ìjọ (Ànábì) Hūd tàbí ìjọ (Ànábì) Sọ̄lih. Ìjọ (Ànábì) Lūt kò sì jìnnà si yín

[90] Kí ẹ sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá).”

[91] Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, a ò gbọ́ àgbọ́yé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ò ń sọ. Dájúdájú àwa sì ń rí ọ ní ọ̀lẹ láààrin wa. Tí kò bá jẹ́ pé nítorí ti ẹbí rẹ ni, a ìbá ti kù ọ́ lókò pa; ìwọ kò sì níí lágbára kan lórí wa

[92] Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé ẹbí mi ló lágbára lójú yin ju Allāhu? Ẹ sì sọ Allāhu di Ẹni tí ẹ kọ̀yìn kọ̀pàkọ́ sí! Dájúdájú Olúwa mi ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[93] Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín, dájúdájú èmi yóò máa bá ẹ̀sìn mi lọ. Láìpẹ́ ẹ̀yin yóò mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, (ẹ̀yin yó sì mọ) ta ni òpùrọ́. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín tí mò ń retí (ìkángun ọ̀rọ̀ yín).”

[94] Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Ṣu‘aeb àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn

[95] Àfi bí ẹni pé wọn kò gbé inú ìlú náà rí. Gbọ́, ìjìnnà sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìran Mọdyan gẹ́gẹ́ bí ìran Thamūd ṣe jìnnà sí ìkẹ́

[96] Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé rán (Ànábì) Mūsā

[97] sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì tẹ̀lé àṣẹ Fir‘aon. Àṣẹ Fir‘aon kò sì jẹ́ ìmọ̀nà

[98] Ó máa ṣíwájú ìjọ rẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa kó wọn wọ inú Iná. Wíwọ Iná náà sì burú

[99] A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ẹ̀bùn ègún tí A fún wọn sì burú

[100] Ìyẹn wà nínú àwọn ìró ìlú tí À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ. Ó wà nínú àwọn ìlú náà èyí tí ó sì ń jẹ́ ìlú àti èyí tí ó ti parẹ́

[101] A ò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun

[102] Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le

[103] Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ẹnikẹ́ni t’ó páyà ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn ni ọjọ́ tí A óò kó àwọn ènìyàn jọ. Àti pé ìyẹn ni ọjọ́ tí gbogbo ẹ̀dá yóò fojú rí

[104] A ò sì fi falẹ̀ bí kò ṣe di àkókò t’ó lọ́jọ́

[105] Ní ọjọ́ t’ó bá dé, ẹ̀mí kan kò níí sọ̀rọ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Olórí burúkú àti olórí ire yó sì wà nínú àwọn ẹ̀dá (ní ọjọ́ náà)

[106] Ní ti àwọn t’ó bá ṣorí burúkú, wọn yóò wà nínú Iná. Wọn yóò máa gbin tòò, wọn yó sì máa ké tòò

[107] Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́ . Dájúdájú Olúwa ni Aṣèyí-ó-wùú

[108] Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ,1 àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́.2 (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin

[109] Nítorí náà, má ṣe wà nínú ròyíròyí nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí kù síbì kan

[110] A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa ẹnu nípa rẹ̀. Àti pé tí kì í bá ṣe ọ̀rọ̀ kan tí ó ti gbawájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, Àwa ìbá ti ṣèdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa al-Ƙur’ān

[111] Dájúdájú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni Olúwa rẹ yóò san ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[112] Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[113] Ẹ má ṣe tẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn t’ó ṣàbòsí nítorí kí Iná má baà fọwọ́ bà yín. Kò sì níí sí àwọn aláàbò fun yín lẹ́yìn Allāhu. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́

[114] Kírun ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọ̀sán (ìyẹn, ìrun Subh, Ṭḥuhr àti ‘Asr) àti ní ìbẹ̀rẹ̀ òru (ìyẹn, ìrun Mọgrib àti ‘Iṣā’). Dájúdájú àwọn iṣẹ́ rere ń pa àwọn iṣẹ́ aburú rẹ́. Ìyẹn ni ìrántí fún àwọn olùrántí (Allāhu)

[115] Ṣe sùúrù. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre

[116] Kí ó sì jẹ́ pé àwọn onílàákàyè kan wà nínú àwọn ìran t’ó ṣíwájú yín (nínú àwọn tí A parẹ́) kí wọ́n máa kọ ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ – àfi ènìyàn díẹ̀ lára àwọn tí A gbàlà nínú wọn. - Àwọn t’ó ṣàbòsí sì tẹ̀lé n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún wọn. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀

[117] Olúwa rẹ kò níí pa àwọn ìlú run lọ́nà àbòsí, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ bá jẹ́ olùṣàtùn-únṣe

[118] Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, ìbá ṣe àwọn ènìyàn ní ìjọ ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo. (Àmọ́) wọn kò níí yé yapa ẹnu (sí ’Islām)

[119] àfi ẹni tí Olúwa rẹ bá kẹ́. Nítorí ìyẹn l’Ó fi ṣẹ̀dá wọn. Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ sì ti ṣẹ (báyìí pé): “Dájúdájú Èmi yóò mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kúnnú iná Jahanamọ.”

[120] Gbogbo (n̄ǹkan tí) À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ nínú àwọn ìró àwọn Òjísẹ́ ni èyí tí A fi ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. Òdodo tún dé bá ọ nínú (sūrah) yìí. Wáàsí àti ìrántí tún ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[121] Kí o sì sọ fún àwọn tí kò gbàgbọ́ pé: "Ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín. Dájúdájú àwa náà yóò máa bá ẹ̀sìn wa lọ

[122] Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí

[123] Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí o sì gbáralé E. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbéra nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

Yúsúfù

Surah 12

[1] ’Alif lām rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá

[2] Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní n̄ǹkan kíké ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè

[3] Àwa ń sọ ìtàn t’ó dára jùlọ fún ọ pẹ̀lú ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (nínú ìmísí) al-Ƙur’ān yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú ìmísí náà ìwọ wà lára àwọn tí kò nímọ̀ (nípa rẹ̀)

[4] (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Yūsuf sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dájúdájú èmi (lálàá) rí àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá, òòrùn àti òṣùpá. Mo rí wọn tí wọ́n forí kanlẹ̀ fún mi.”

[5] Ó sọ pé: "Ọmọ mi, má ṣe rọ́ àlá rẹ fún àwọn ọbàkan rẹ nítorí kí wọ́n má baà déte sí ọ. Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn

[6] Báyẹn ni Olúwa rẹ yóò ṣe ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó máa fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́. Ó sì máa pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún ìwọ àti àwọn ẹbí Ya‘ƙūb, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe pé e ṣíwájú fún àwọn bàbá rẹ méjèèjì, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ishāƙ. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[7] Dájúdájú àwọn àmì (àríwòye) ń bẹ fún àwọn oníbèéèrè nípa (ìtàn Ànábì) Yūsuf àti àwọn ọbàkan rẹ̀

[8] (Rántí) nígbà tí wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀ ni bàbá wa nífẹ̀ẹ́ sí ju àwa. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni àwa. Dájúdájú bàbá wa mà ti wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé

[9] Ẹ pa Yūsuf tàbí kí ẹ lọ gbé e jùnù sí ilẹ̀ (mìíràn) nítorí kí bàbá yín lè rójú gbọ́ tiyín. Ẹ sì máa di ènìyàn rere lẹ́yìn rẹ̀

[10] Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: "Ẹ má ṣe pa Yūsuf. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ ṣá fẹ́ wá n̄ǹkan ṣe (sí ọ̀rọ̀ rẹ̀), ẹ gbé e jù sínú ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga nítorí kí apá kan nínú àwọn onírìn-àjò lè baà he é lọ

[11] Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni kò mú ọ fi ọkàn tán wa lórí Yūsuf. Dájúdájú àwa sì máa jẹ́ olùtọ́jú rẹ̀

[12] Jẹ́ kí ó bá wa lọ ní ọ̀la nítorí kí ó lè dára yá, kí ó sì lè ṣeré. Àti pé dájúdájú àwa ni olùṣọ́ fún un.”

[13] Ó sọ pé: “Dájúdájú ó máa bà mí nínú jẹ́ pé kí ẹ mú u lọ. Mo sì ń páyà kí ìkokò má lọ pa á jẹ nígbà tí ẹ̀yin bá gbàgbé rẹ̀ (síbì kan).”

[14] Wọ́n sọ pé: “Tí ìkokò bá fi pa á jẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni wá, dájúdájú àwa nígbà náà ni ẹni òfò.”

[15] Nígbà tí wọ́n mú un lọ tán, wọ́n panupọ̀ pé kí àwọn jù ú sí ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga. À si fí ìmísí ránṣẹ́ sí Yūsuf pé: “Dájúdájú ìwọ yóò fún wọn ní ìró nípa ọ̀rọ̀ wọn yìí nígbà tí wọn kò níí fura.”

[16] Wọ́n dé bá bàbá wọn ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń sunkún

[17] Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, àwa lọ díje eré sísá. A sì fi Yūsuf sílẹ̀ síbi àwọn ẹrù wa. Nígbà náà ni ìkokò pa á jẹ. Ìwọ kò sì níí gbà wá gbọ́, àwa ìbáà jẹ́ olódodo.”

[18] Wọ́n dé pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ irọ́ lára ẹ̀wù rẹ̀. (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: "Rárá o, ẹ̀mí yín l’ó ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fun yín. Nítorí náà, sùúrù abiyì (lọ̀rọ̀ mi kàn). Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ lórí ohun tí ẹ̀ ń ròyìn

[19] Àwọn onírìn-àjò kan sì dé. Wọ́n rán apọnmi wọn (ní omi). Ó sì ju doro rẹ̀ sínú kànǹga. (Yūsuf sì dìrọ̀ mọ́ okùn doro bọ́ síta. Apọnmi sì) sọ pé: "Ire ìdùnnú rè é! Èyí ni ọmọdékùnrin." Wọ́n sì fi pamọ́ fún títà (bí ọjà). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[20] Wọ́n tà á ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú owó diriham t’ó níye. Wọ́n sì jẹ́ ẹni t’ó mú un bín-íntín

[21] Ẹni tí ó rà á ní (ìlú) Misrọ sọ fún aya rẹ̀ pé: “Ṣe ibùgbé rẹ̀ dáadáa. Ó súnmọ́ kí ó wúlò fún wa tàbí kí á fi ṣọmọ.” Báyẹn ni A ṣe fi àyè gba Yūsuf lórí ilẹ̀. Àti pé kí Á tún lè fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́n. Allāhu ni Olùborí lórí àṣẹ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀

[22] Nígbà tí ó di géńdé tán, A fún un ní ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san rere

[23] Obìnrin tí Yūsuf wà nínú ilé rẹ̀ sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì ti gbogbo ìlẹ̀kùn pa. Ó sọ pé: “Súnmọ́ mi.” (Yūsuf) sọ pé: “Mo sádi Allāhu. Dájúdájú ọkọ rẹ ni ọ̀gá mi. Ó sì ṣe ibùgbé mi dáadáa. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”

[24] (Obìnrin náà) kúkú gbèrò eré ìfẹ́ sí i. Òun náà gbèrò rẹ̀, Tí kì í bá ṣe pé ó rí ẹ̀rí Olúwa rẹ̀ (pé harāmu ni sìná, ìbá súnmọ́ ọn). Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ náà rí) nítorí kí Á lè ṣẹ́rí aburú àti sìná ṣíṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn ẹni ẹ̀ṣà

[25] Àwọn méjèèjì sáré lọ síbi ìlẹ̀kùn. (Obìnrin yìí) sì fa ẹ̀wù (Yūsuf) ya lẹ́yìn. Àwọn méjèèjì sì bá ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà. (Obìnrin yìí) sì sọ pé: “Kí ni ẹ̀san fún ẹni tí ó gbèrò aburú sí ará ilé rẹ bí kò ṣe pé kí á sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.”

[26] (Yūsuf) sọ pé: “Òun l’ó jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ mi.” Ẹlẹ́rìí kan nínú ará ile (obìnrin náà) sì jẹ́rìí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya níwájú, (obìnrin yìí) l’ó sọ òdodo, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn òpùrọ́

[27] Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya lẹ́yìn, (obìnrin yìí) l’ó parọ́, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn olódodo

[28] Nígbà tí (ọkọ) rí ẹ̀wù rẹ̀ tí wọ́n ti fà á ya lẹ́yìn, ó sọ pé: "Dájúdájú nínú ète ẹ̀yin obìnrin ni (èyí). Dájúdájú ète yín tóbi

[29] Yūsuf, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Kí ìwọ (obìnrin yìí) sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn aláṣìṣe

[30] Àwọn obìnrin kan nínú ìlú sọ pé: “Ayaba ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀; ìfẹ́ kúkú ti kó sí i lọ́kàn. Dájúdájú àwa ń rí òun pé ó wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.”

[31] Nígbà tí (ayaba) gbọ́ ète (ọ̀rọ̀) wọn (tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀), ó ránṣẹ́ sí wọn. Ó sì pèsè ohun jíjẹ àjókòójẹ sílẹ̀ fún wọn. Ó fún ìkọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀bẹ (tí ó máa fi jẹun). Ó sì sọ pé: “Jáde sí wọn, (Yūsuf).” Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n gbé e tóbi (fún ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì rẹ́ra wọn lọ́wọ́ (fún ìyanu ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì wí pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu! Èyí kì í ṣe abara. Kí ni èyí bí kò ṣe mọlāika alápọ̀n-ọ́nlé.”

[32] (Ayaba) sọ pé: “Ìyẹn ni ẹni tí ẹ bú mi fún. Dájúdájú mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wá ìṣọ́ra. Dájúdájú tí kò bá ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún un, wọ́n kúkú máa fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni. Dájúdájú ó sì máa wà nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ.”

[33] (Yūsuf) sọ pé: “Olúwa (Ẹlẹ́dàá) mi, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo nífẹ̀ẹ́ sí ju ohun tí wọ́n ń pè mí sí. Tí O ò bá sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò kó sínú ète wọn, èmi yó sì wà lára àwọn aláìmọ̀kan.”

[34] Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ jẹ́pè rẹ̀. Ó sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[35] Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti rí àwọn àmì (pé Yūsuf kò jẹ̀bi ẹ̀sùn), lẹ́yìn náà, ó hàn sí wọn pé àwọn gbọ́dọ̀ sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di àsìkò kan ná

[36] Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì kan wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì sọ pé: “Èmi lálàá rí ara mi pé mò ń fún ọtí.” Ẹnì kejì sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí ara mi pé mo gbé búrẹ́dì rù sórí mi, ẹyẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.” Sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú àwọn ẹni rere

[37] Ó sọ pé: "Oúnjẹ tí wọ́n ń pèsè fun yín kò ní tí ì dé ba yín, àfi kí èmi ti sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún ẹ̀yin méjèèjì ṣíwájú kí ó tó dé ba yín. Ìyẹn wà nínú n̄ǹkan tí Olúwa mi fi mọ̀ mí. Dájúdájú èmi fi ẹ̀sìn àwọn ènìyàn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu sílẹ̀. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[38] Mo sì tẹ̀lé ẹ̀sìn àwọn bàbá mi, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb. Kò tọ́ sí wa pé kí á sọ n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ fún Allāhu. Ìyẹn wà nínú oore àjùlọ Allāhu lórí àwa àti lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Allāhu)

[39] Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ṣé àwọn olúwa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ l’ó lóore jùlọ (láti jọ́sìn fún) tàbí Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí

[40] Kò sí ohun kan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ sọ wọ́n - ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín - Allāhu kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un. Ìdájọ́ (ta ni ìjọ́sìn tọ́ sí) kò sí fún ẹnì kan àfi Allāhu. Ó sì ti pàṣẹ pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Òun nìkan. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀

[41] Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ní ti ẹnì kan nínú yín, ó máa fún ọ̀gá rẹ̀ ní ọtí mu. Ní ti ẹnì kejì, wọn yóò kàn án mọ́ igi, ẹyẹ yó sì máa jẹ nínú orí rẹ̀. Wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe ìbéèrè nípa rẹ̀

[42] Ó sì sọ fún ẹni tí ó rò pé ó máa là nínú àwọn méjèèjì pé: “Rántí mi lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ.” Èṣù sì mú (Yūsuf) gbàgbé ìrántí Olúwa rẹ̀ (nípa wíwá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀). Nítorí náà, ó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n fún àwọn ọdún díẹ̀

[43] Ọbá sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí màálù méje t’ó sanra. Àwọn màálù méje t’ó rù sì ń jẹ wọ́n. (Mo tún lálàá rí) ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ fún mi ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá mi tí ẹ bá jẹ́ ẹni t’ó máa ń túmọ̀ àlá.”

[44] Wọ́n sọ pé: “Àwọn àlá t’ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn (nìyí). Àti pé àwa kì í ṣe onímọ̀ nípa ìtúmọ̀ àwọn àlá.”

[45] Ẹni tí ó là nínú àwọn (ẹlẹ́wọ̀n) méjèèjì sọ pé, - ó rántí (Yūsuf) lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ -: “Èmi yóò fun yín ní ìró nípa ìtúmọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fi iṣẹ́ rán mi ná (kí n̄g lọ ṣe ìwádìí rẹ̀).”

[46] Yūsuf, ìwọ olódodo, fún wa ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá (yìí): màálù méje t’ó sanra. Àwọn màálù méje t’ó rù sì ń jẹ wọ́n. Àti ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. (Kí ni ìtúmọ̀ rẹ̀) nítorí kí n̄g lè fi àbọ̀ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn àti nítorí kí wọ́n lè mọ (ìtúmọ̀ rẹ̀)

[47] Ó sọ pé: “Ẹ̀yin yóò gbin n̄ǹkan ọ̀gbìn fún ọdún méje gbáko (gẹ́gẹ́ bí) ìṣe (yín). Ohunkòhun tí ẹ bá kó lérè oko, kí ẹ fi sílẹ̀ sínú ṣiri rẹ̀ àfi díẹ̀ tí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀

[48] Lẹ́yìn náà, ọdún méje t’ó le (fún ọ̀dá òjò) yóò dé lẹ́yìn ìyẹn, (àwọn ará ìlú) yó sì lè jẹ ohun tí ẹ ti (kó lérè oko) ṣíwájú àfi díẹ̀ tí ẹ máa fi pamọ́ (fún gbígbìn)

[49] Lẹ́yìn náà, ọdún kan tí Wọn yóò rọ̀jò fún àwọn ènìyàn yóò dé lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn ènìyàn yó sì máa fún èso àti wàrà mu nínú ọdún náà

[50] Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi.” Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ rẹ. (Yūsuf) sọ pé: “Padà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o bi í léèrè pé, kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin tí wọ́n rẹ́ ọwọ́ ara wọn. Dájúdájú Olúwa mi ni Onímọ̀ nípa ète wọn.”

[51] (Ọba) sọ pé: "Kí ni ọ̀rọ̀ tiyín ti jẹ́ tí ẹ fi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ Yūsuf?" Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu. àwa kò mọ aburú kan mọ Yūsuf.” Ayaba sọ pé: “Nísinsìn yìí ni òdodo fojú hàn. Èmi ni mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn olódodo.”

[52] (Yūsuf sọ pé): "Ìyẹn nítorí kí ọba lè mọ̀ pé dájúdájú èmi kò jàǹbá rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ìmọ̀nà síbi ète àwọn oníjàǹbá

[53] Èmi kò sì fọra mi mọ́ (níbi èròkérò); dájúdájú ẹ̀mí kúkú ń pàṣẹ èròkérò (fún ẹ̀dá) ni àfi ẹni tí Olúwa mi bá kẹ́. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[54] Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi. Èmi yóò ṣe é ní ẹni ẹ̀ṣà lọ́dọ̀ mi.” Nígbà tí ọba bá a sọ̀rọ̀ tán, ó sọ pé: “Lọ́dọ̀ wa ní òní dájúdájú ìwọ ni ẹni pàtàkì, olùfọkàntán.”

[55] (Yūsuf) sọ pé: “Fi mí ṣe aláṣẹ àwọn ọrọ̀ ìlú, dájúdájú alámòjúútó onímọ̀ ni mí.”

[56] Báyẹn ni A ṣe fún Yūsuf ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. Ó sì ń gbé ní ibi tí ó bá fẹ́. Àwa ń mú ìkẹ́ Wa bá ẹnikẹ́ni tí A bá fẹ́. A ò sì níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre

[57] Dájúdájú ẹ̀san ti ọ̀run lóore jùlọ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu)

[58] Àwọn ọbàkan (Ànábì) Yūsuf dé, wọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́. Ó dá wọn mọ̀. Àwọn kò sì mọ̀ ọ́n mọ́

[59] Nígbà tí ó sì bá wọn di ẹrù oúnjẹ wọn tán, ó sọ pé: "Ẹ lọ mú ọbàkan yín wá láti ọ̀dọ̀ bàbá yín. Ṣé ẹ kò rí i pé dájúdájú mò ń wọn kóńgò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni? Èmi sì dára jùlọ nínú àwọn olùgbàlejò

[60] Tí ẹ ò bá sì mú un wá, kò sí (ẹrù oúnjẹ) wíwọ̀n fun yín lọ́dọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ mi

[61] Wọ́n sọ pé: “A máa jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún un lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Dájúdájú àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.”

[62] Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ fi owó-ọjà wọn sínú ẹrù (oúnjẹ) wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ nígbà tí wọ́n bá padà dé ọ̀dọ̀ ará ilé wọ́n (pé a ti dá a padà fún wọn), wọn yó sì lè padà wá.”

[63] Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ bàbá wọn, wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, wọ́n kọ̀ láti wọn oúnjẹ fún wa. Nítorí náà, jẹ́ kí ọbàkan wa bá wa lọ nítorí kí á lè rí oúnjẹ wọ̀n (wálé). Dájúdájú àwa ni olùṣọ́ fún un.”

[64] Ó sọ pé: “Ṣé kí n̄g gbà yín gbọ́ lórí rẹ̀ bí kò ṣe bí mó ṣe gbà yín gbọ́ ní ìṣaájú lórí ọmọ-ìyá rẹ̀? Nítorí náà, Allāhu lóore jùlọ ní Olùṣọ́. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

[65] Nígbà tí wọ́n tú ẹrù oúnjẹ wọn, wọ́n rí owó-ọjà wọn tí wọ́n dá padà fún wọn (nínú rẹ̀). Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni a tún ń fẹ́? Owó-ọjà wa nìyí tí wọ́n ti dá padà fún wa. A ó si tún fi wá oúnjẹ rà fún àwọn ẹbí wa. A ó sì dáàbò bo ọbàkan wa. A sì máa rí àlékún ẹrù oúnjẹ (tí) ràkúnmí kan lè rù sí i. Ìwọ̀n oúnjẹ kékeré sì nìyẹn (lọ́dọ̀ ọba).”

[66] Ó sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́ kí ó ba yín lọ títí ẹ máa fi ṣe àdéhùn fún mi ní (orúkọ) Allāhu pé dájúdájú ẹ máa mú un padà wá bá mi àfi tí (àwọn ọ̀tá) bá ka yín mọ́.” Nígbà tí wọ́n fún un ní àdéhùn wọn tan, ó sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”

[67] Ó tún sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe gba ẹnu ọ̀nà ẹyọ kan wọlé. Ẹ gba ẹnu ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọlé. Èmi kò lè fí n̄ǹkan kan rọ̀ yín lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sí ìdájọ́ (fún ẹnì kan) àfi fún Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.”

[68] Nígbà tí wọ́n wọ (inú ìlú) ní àwọn àyè tí bàbá wọn pa láṣẹ fún wọn, kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe bùkátà kan nínú ẹ̀mí (Ànábì) Ya‘ƙūb tí ó múṣẹ. Dájúdájú onímọ̀ ni nípa ohun tí A fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀

[69] Nígbà tí wọ́n wọlé ti (Ànábì) Yūsuf, ó mú ọmọ-ìyá rẹ̀ mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi ni ọmọ-ìyá rẹ. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.”

[70] Nígbà tí ó sì bá wọn di ẹrù wọn tán, ó fi ife-ìmumi sínú ẹrù ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan kéde pé: “Ẹ̀yin èrò-ràkúnmí, dájúdájú ẹ̀yin ni olè.”

[71] Wọ́n dojú kọ wọ́n, wọ́n sọ pé: “Kí l’ẹ ṣàfẹ́kù?”

[72] Wọ́n sọ pé: “A ò rí ife ọba ni. Ẹni tí ó bá sì mú un wá yóò rí ẹrù oúnjẹ ràkúnmí kan gbà. Èmi sì ni onídùróó fún ẹ̀bùn náà.”

[73] Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra, dájúdájú ẹ mọ̀ pé a kò wá láti ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Àti pé àwa kì í ṣe olè.”

[74] Wọ́n sọ pé: “Kí ni ẹ̀san (fún ẹni tí) ó jí i, tí (ó bá hàn pé) ẹ̀yin jẹ́ òpùrọ́?”

[75] Wọ́n sọ pé: “Ẹ̀san rẹ̀; ẹni tí wọ́n bá bá a nínú ẹrù rẹ̀, òun náà ni ẹ̀san rẹ̀. Báyẹn ni àwa náà ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san.”

[76] Ó sì bẹ̀rẹ̀ (àyẹ̀wò) àpò wọn ṣíwájú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú un jáde láti inú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Báyẹn ní A ṣe fún (Ànábì) Yūsuf ní ète dá. Kò lè fi òfin ọba mú ọmọ-ìyá rẹ̀ àfi tí Allāhu bá fẹ́. À ń ṣàgbéga fún ẹnikẹ́ni tí A bá fẹ́. Onímọ̀ wà lókè gbogbo onímọ̀

[77] Wọ́n sọ pé: “Tí ó bá jalè, dájúdájú ọmọ-ìyá rẹ̀ kan ti jalè ṣíwájú.” (Ànábì) Yūsuf sì fi ọ̀rọ̀ náà pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀, kò sì fi hàn sí wọn pé (kò rí bẹ́ẹ̀). Ó (sì) sọ pé: “Ipò tiyín l’ó buru jùlọ. Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ.”

[78] Wọ́n sọ pé: "Ìwọ ọba, dájúdájú ó ní bàbá arúgbó àgbàlágbà kan. Nítorí náà, mú ẹnì kan nínú wa dípò rẹ̀. Dájúdájú àwa ń rí ìwọ pé o wà nínú àwọn ẹni-rere

[79] Ó sọ pé: “Mo sádi Allāhu pé kí á mú ẹnì kan àfi ẹni tí a bá ẹrù wa lọ́dọ̀ rẹ. (Tí a bá mú ẹlòmíìràn) dájúdájú nígbà náà alábòsí ni wá.”

[80] Nígbà tí wọ́n sọ̀rètí nù nípa rẹ̀, wọ́n tẹ̀ sọ̀rọ̀. Àgbà (nínú) wọn sọ pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé dájúdájú bàbá yín ti gba àdéhùn yín tí (ẹ ṣe ní orúkọ) Allāhu. Àti pé ṣíwájú (èyí, ẹ ti ṣe) àṣeètó nípa ọ̀rọ̀ (Ànábì) Yūsuf. Nítorí náà, èmi kò níí fi ilẹ̀ (Misrọ) sílẹ̀ títí bàbá mi yóò fi yọ̀ǹda fún mi tàbí (títí) Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ fún mi. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́

[81] Ẹ padà sọ́dọ̀ bàbá yín, kí ẹ sì sọ pé: “Bàbá wa, dájúdájú ọmọ rẹ jalè. A kò sì lè jẹ́rìí (sí kiní kan) àfi ohun tí a bá nímọ̀ (nípa) rẹ̀. Àwa kò sì jẹ́ olùṣọ́ fún ohun tí ó pamọ́ (fún wa)

[82] Kí o sì bi àwọn ará ìlú tí a wà nínú rẹ̀ àti èrò-ràkúnmí tí a jọ darí dé léèrè wò. Dájúdájú olódodo mà ni wá.”

[83] (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fun yín. Nítorí náà, sùúrù t’ó rẹwà (lọ̀rọ̀ mi kàn báyìí). Ó ṣeé ṣe kí Allāhu bá mi mú gbogbo wọn wá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”

[84] Ó pa wọ́n tì, ó sì sọ pé: “Ìbànújẹ́ ń bẹ fún mi lórí Yūsuf!” Ojú rẹ̀ méjèèjì sì funfun wá (kò sì ríran mọ́); ó sì pa ìbànújẹ́ mọ́ra

[85] Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra, ìwọ kò yé rántí Yūsuf títí o máa fi di yánnayànna tàbí (títí) o máa fi di ara àwọn òkú.”

[86] Ó sọ pé: “Allāhu mà ni èmi ń ro ẹ̀dùn ọkàn mi àti ìbànújẹ́ mi fún. Mo sì mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu

[87] Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ lọ wádìí nípa Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀. Ẹ sì má ṣe sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu àfi ìjọ aláìgbàgbọ́.”

[88] Nìgbà tí wọ́n wọlé tọ Yūsuf, wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, ìnira ti mú àwa àti ará ilé wa. A sì mú owó kan tí kò yanjú wá. Nítorí náà, wọn kóńgò (oúnjẹ) náà kún fún wa, kí ó sì ta wá lọ́rẹ. Dájúdájú Allāhu yóò san àwọn olùtọrẹ ní ẹ̀san rere.”

[89] Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ẹ ṣe fún Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìmọ̀kan.”

[90] Wọ́n sọ pé: “Ṣé dájúdájú ìwọ ni Yūsuf?” Ó sọ pé: “Èmi ni Yūsuf. Ọmọ-ìyá mi sì nìyí. Dájúdájú Allāhu ti ṣe ìdẹ̀ra fún wa. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu), tí ó sì ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.”

[91] Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra! Dájúdájú Allāhu ti gbọ́lá fún ọ jù wá lọ. Àti pé dájúdájú àwa ni aláṣìṣe.”

[92] Ó sọ pé: "Kò sí ìbáwí fun yín ní òní. Allāhu yóò foríjìn yín. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú

[93] Ẹ mú ẹ̀wù mi yìí lọ, kí ẹ fi lé iwájú bàbá mi, ó máa padà di olùríran. Kí ẹ sì kó gbogbo ẹbí yín wá bá mi

[94] Nígbà tí èrò-ràkúnmí náà sí pínyà (kúrò lọ́dọ̀ Ànábì Yūsuf), bàbá wọn sọ pé: “Dájúdájú èmi ń gbọ́ òórùn Yūsuf tí ẹ ò bá níí sọ pé mò ń jarán.”

[95] Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra! Dájúdájú ìwọ sì wà nínú àṣìṣe rẹ ti àtijọ́ (nípa ìfẹ́ Yūsuf).”

[96] Nígbà tí oníròó-ìdùnnú dé, ó ju (ẹ̀wù náà) lé e níwájú, ó sì ríran padà. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ n̄g kò sọ fun yín pé dájúdájú èmi mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu.”

[97] Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, tọrọ àforíjìn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa, dájúdájú àwa jẹ́ aláṣìṣe.”

[98] Ó sọ pé: “Láìpẹ́ mo máa tọrọ àforíjìn fun yín lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

[99] Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Yūsuf, ó kó àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ wọ ìlú Misrọ ní olùfàyàbalẹ̀ – tí Allāhu bá fẹ́.-”

[100] Ó gbé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì sórí ìtẹ́. Wọ́n sì dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni. Ó sọ pé: “Bàbá mi, èyí ni ìtúmọ̀ àlá mi (tí mo lá) ṣíwájú. Dájúdájú Olúwa mi ti sọ ọ́ di òdodo. Ó sì ṣe dáadáa fún mi nígbà tí Ó mú mi jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó tún mu yín wá (bá mi) láti inú oko lẹ́yìn tí Èṣù ti ba ààrin èmi àti àwọn ọbà-kan mi jẹ́. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú fún ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[101] Olúwa mi, dájúdájú O ti fún mi ni ìjọba. O tún fún mi ni ìmọ̀ ìtúmọ̀ àlá. Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Ìwọ ni Olùrànlọ́wọ́ mi ní ayé àti ní ọ̀run, pa mi sípò mùsùlùmí. Kí O sì fi mí pẹ̀lú àwọn ẹni rere.”

[102] Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí A fi ìmísí (rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Àti pé ìwọ kò sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n panu pọ̀ lórí ọ̀rọ̀ wọn, tí wọ́n ń déte

[103] Ìwọ ìbáà ṣojú kòkòrò (ìgbàlà wọn), ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò níí gbàgbọ́

[104] Ìwọ kò sì bi wọ́n léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá

[105] Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn àmì tí ń bẹ ní sánmọ̀ àti ní orí ilẹ̀ tí wọ́n ń ré kọjá lórí rẹ̀, tí wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀

[106] Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni kò níí gba Allāhu gbọ́ ní òdodo àfi kí wọ́n tún máa ṣẹbọ

[107] Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ pé ohun tí ń bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ nínú ìyà Allāhu kò lè dé bá àwọn ni tàbí pé Àkókò náà kò lè kò lé àwọn lórí ní òjijì, tí wọn kò sì níí fura

[108] Sọ pé: “Èyí ni ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) mi, èmi àti àwọn t’ó tẹ̀lé mi sì ń pèpè sí (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú ìmọ̀ àmọ̀dájú. Mímọ́ ni fún Allāhu. Èmi kò sì sí lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

[109] A ò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí nínú àwọn ará ìlú. Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Dájúdájú Ilé ìkẹ́yìn lóore jùlọ fún àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni

[110] (A kì í jẹ àwọn ènìyàn níyà) títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ bá t’ó sọ̀rètí nù (nípa ìgbàgbọ́ wọn), tí wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n ti pe àwọn ní òpùrọ́. Àrànṣe Wa yó sì dé bá wọn. A sì máa gba ẹni tí A bá fẹ́ là. Wọn kò lè dá ìyà Wa padà lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀

[111] Dájúdájú àríwòye wà nínú ìtàn wọn fún àwọn onílàákàyè. (Al-Ƙur’ān) kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń hun, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí t’ó jẹ́ òdodo nínú èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣàlàyé gbogbo n̄ǹkan; ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo

Ààrá

Surah 13

[1] ’Alif lām mīm rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà. Àti pé òdodo ni ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò gbàgbọ́

[2] Allāhu ni Ẹni tí Ó gbé àwọn sánmọ̀ ga sókè láì sí àwọn òpó kan (fún un) tí ẹ lè fojú rí. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Ó ń ṣe àlàyé àwọn āyah nítorí kí ẹ lè mọ àmọ̀dájú nípa ìpàdé Olúwa yín

[3] Òun ni Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹsẹ. Ó sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ àti àwọn odò. Àti pé nínú gbogbo àwọn èso, Ó ṣe é ní oríṣi méjì-méjì. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀

[4] Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) t’ó wà nítòsí ara wọn àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù t’ó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fi omi ẹyọ kan wọn. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi jíjẹ. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè

[5] Tí o bá ṣèèmọ̀, èèmọ̀ mà ni ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn (nípa bí wọ́n ṣe sọ pé): “Ṣé nígbà tí a bá ti di erùpẹ̀ tán, ṣé nígbà náà ni àwa yóò tún di ẹ̀dá titun?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀wọ̀n ń bẹ lọ́rùn wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[6] Wọ́n tún ń kán ọ lójú pé kí aburú ṣẹlẹ̀ ṣíwájú rere. Àwọn àpẹ̀ẹrẹ ìyà kúkú ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú wọn. Àti pé dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn fún àwọn ènìyàn lórí àbòsí (ọwọ́) wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ le níbi ìyà

[7] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Olùkìlọ̀ mà ni ìwọ. Olùtọ́sọ́nà sì wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan

[8] Allāhu mọ ohun tí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní lóyún àti ohun tí ilé ọmọ yóò fi dín kù (nínú ọjọ́ ìbímọ) àti ohun tí ó máa fi lékún. N̄ǹkan kọ̀ọ̀kan l’ó sì ní òdíwọ̀n lọ́dọ̀ Rẹ̀

[9] (Allāhu ni) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti- gban̄gba. Ó tóbi, Ó ga

[10] Bákan náà ni (lọ́dọ̀ Allāhu), ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ pamọ́ sínú nínú yín àti ẹni tí ó sọ ọ́ síta pẹ̀lú ẹni tí ó fi òru bojú àti ẹni tí ó ń rìn kiri ní ọ̀sán

[11] Ó ń bẹ fún ènìyàn (kọ̀ọ̀kan) àwọn mọlāika tí ń gbaṣẹ́ fúnra wọn; wọ́n wà níwájú (ènìyàn) àti lẹ́yìn rẹ̀; wọ́n ń ṣọ́ (iṣẹ́ ọwọ́) rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà n̄ǹkan t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ ìjọ kan títí wọn yóò fi yí n̄ǹkan t’ó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn padà. Nígbà tí Allāhu bá gbèrò aburú kan ro ìjọ kan, kò sí ẹni t’ó lè dá a padà. Kò sì sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀

[12] Òun ni Ẹni t’ó ń fi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ìbẹ̀rù àti ní ìrètí (fun yín). Ó sì ń ṣẹ̀dá ẹ̀ṣújò t’ó ṣú dẹ̀dẹ̀

[13] Àrá ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Un, àwọn mọlāika ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìbẹ̀rù Rẹ̀. Ó ń rán iná àrá níṣẹ́. Ó sì ń fi kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Síbẹ̀ wọ́n ń jiyàn nípa Allāhu. Ó sì le níbi gbígbá-ẹ̀dá-mú

[14] TiRẹ̀ ni ìpè òdodo. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè fi kiní kan jẹ́ pè wọn àfi bí ẹni tí ó tẹ́wọ́ rẹ̀ méjèèjì (lásán) sí omi nítorí kí omi lè dé ẹnu rẹ̀. Omi kò sì lè dé ẹnu rẹ̀. Àdúà àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà

[15] Allāhu ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń forí kanlẹ̀ fún, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, - òòji wọn (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀) - ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́

[16] Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé lẹ́yìn Rẹ̀ ni ẹ tún mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan, tí wọn kò ní ìkápá oore àti ìnira fún ẹ̀mí ara wọn?” Sọ pé: “Ṣé afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Tàbí àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ dọ́gba? Tàbí wọ́n yóò fún Allāhu ní àwọn akẹgbẹ́ kan tí àwọn náà dá ẹ̀dá bíi ti ẹ̀dá Rẹ̀, (tó bẹ́ẹ̀ gẹ́) tí ẹ̀dá fi jọra wọn lójú wọn?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí

[17] Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Àwọn ojú-odò sì ń ṣàn pẹ̀lú òdiwọ̀n rẹ̀. Àgbàrá sì ń gbé ìfòfó orí-omi lọ. Bákan náà, nínú n̄ǹkan tí wọ́n ń yọ́ nínú iná láti fi ṣe n̄ǹkan-ọ̀ṣọ́ tàbí n̄ǹkan-èlò, òhun náà ní ìfòfó bí irú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àpèjúwe òdodo àti irọ́ wá. Ní ti ìfòfó, ó máa bá pàǹtí lọ. Ní ti èyí tí ó sì máa ṣe ènìyàn ní àǹfààní, ó máa dúró sí orí ilẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àpèjúwe wá

[18] Ohun rere wà fún àwọn t’ó jẹ́pè Olúwa wọn. Àwọn tí kò sì jẹ́pè Rẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé tiwọn ni gbogbo n̄ǹkan t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni aburú ìṣírò-iṣẹ́ wà fún. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; ibùgbé náà sì burú

[19] Ǹjẹ́ ẹni tí ó mọ̀ pé òdodo kúkú ni n̄ǹkan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹni tí ó fọ́jú (nípa rẹ̀)? Àwọn onílàákàyè l’ó ń lo ìrántí

[20] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń mú àdéhùn Allāhu ṣẹ. Àti pé wọn kì í tú àdéhùn

[21] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń da ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀ pọ̀. Wọ́n ń páyà Olúwa wọn. Wọ́n sì ń páyà aburú ìṣírò-iṣẹ́

[22] (Àwọn ni) àwọn t’ó ṣe sùúrù láti fi wá Ojú rere Olúwa wọn. Wọ́n ń kírun. Wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Wọ́n sì ń fi rere ti aburú lọ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àtubọ̀tán Ilé rere ń bẹ fún

[23] Inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ̀, (àwọn) àti ẹni t’ó bá ṣe rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Àwọn mọlāika yó sì máa wọlé tọ̀ wọ́n láti ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan

[24] (Wọn yóò sọ pé): “Àlàáfíà fun yín nítorí ìfaradà yín.” Àtubọ̀tán Ilé náà sì dára

[25] Àwọn t’ó ń tú àdéhùn Allāhu lẹ́yìn tí wọ́n ti gba àdéhùn Rẹ̀, tí wọ́n ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀; àwọn wọ̀nyẹn ni ègún wà fún. Àti pé Ilé (Iná) burúkú wà fún wọn

[26] Allāhu ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́). Wọ́n sì dunnú sí ìṣẹ̀mí ilé ayé! Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé ní ẹ̀gbẹ́ ti ọ̀run bí kò ṣe ìgbádùn bín-íntín

[27] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ṣẹ́rí sọ́dọ̀ Rẹ̀.”

[28] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ pẹ̀lú ìrántí Allāhu; ẹ gbọ́, pẹ̀lú ìrántí Allāhu ni àwọn ọkàn máa fi balẹ̀

[29] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, orí ire àti àbọ̀ rere wà fún wọn

[30] Báyẹn ni A ṣe rán ọ níṣẹ́ sí ìjọ kan, (èyí tí) àwọn ìjọ kan kúkú ti ré kọjá lọ ṣíwájú wọn, nítorí kí o lè máa kà fún wọn n̄ǹkan tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ní ìmísí. Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé. Sọ pé: “Òun ni Olúwa mi. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”

[31] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú Ƙur’ān, wọ́n fi mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn), tàbí wọ́n fi gélè (láti yanu), tàbí wọ́n fi bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ (wọ́n sì jí dìde, wọn kò níí gbàgbọ́). Àmọ́ sá, ti Allāhu ni gbogbo àṣẹ pátápátá. Ṣé àwọn t’ó gbàgbọ́ kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá tọ́ gbogbo ènìyàn sọ́nà. Àjálù kò sì níí yé ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ tàbí (àjálù náà kò níí yé) sọ̀kalẹ̀ sí tòsí ilé wọn títí di ìgbà tí àdéhùn Allāhu yóò fi dé. Dájúdájú Allāhu kò níí yapa àdéhùn

[32] Dájúdájú wọn ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ. Mo sì lọ́ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)

[33] Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ń mójútó ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí ó ṣe (dà bí ẹni tí kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Síbẹ̀) ẹ tún bá Allāhu wá àwọn akẹgbẹ́ kan! Sọ pé: “Ẹ dárúkọ wọn ná.” Tàbí ẹ̀yin yóò fún (Allāhu) ní ìró ohun tí kò mọ̀ lórí ilẹ̀ tàbí (ẹ̀yin yóò pa) irọ́ funfun báláú ni? Wọ́n kúkú ti ṣe ète ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Wọ́n sì ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà òdodo. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sì níí sí olùtọ́sọ́nà kan fún un

[34] Ìyà wà fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Ìyà ti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kúkú gbópọn jùlọ. Kò sì níí sì aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu

[35] Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra tí Wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (ni èyí tí) àwọn odò ń ṣàn kọjá nísàlẹ̀ rẹ̀. Èso rẹ̀ àti ibòji rẹ̀ yó sì máa wà títí láéláé. Ìyẹn ni ìkángun àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu). Iná sì ni ìkángun àwọn aláìgbàgbọ́

[36] Àwọn tí A fún ní Tírà ń dunnú sí ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sì wà nínú àwọn ìjọ kèfèrí-parapọ̀ t’ó ń ṣe àtakò sí apá kan rẹ̀. Sọ pé: “N̄ǹkan tí Wọ́n pa mí láṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu. Èmi kò sì gbọdọ̀ wá akẹgbẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni mò ń pèpè sí. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.”

[37] Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní ìdájọ́ pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. Dájúdájú tí o bá fi lè tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn, lẹ́yìn n̄ǹkan tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kò sí aláàbò àti olùṣọ́ kan fún ọ mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu

[38] Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.1 Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu.2 Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ l’ó ní àkọsílẹ̀

[39] Allāhu ń pa ohun tí Ó bá fẹ́ rẹ́. Ó sì ń mú (ohun tí Ó bá fẹ́) ṣẹ. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Tírà Ìpìlẹ̀ wà. bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ẹ̀dá kò tí ì máa jẹ́ ẹ̀dá títí dé ìkángun ẹ̀dá nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra tàbí nínú Iná. Nínú àkọsílẹ̀ yìí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti ń yọ àkọsílẹ̀ ọlọ́dọọdún fún àwọn mọlāika Rẹ̀. Nítorí náà ohun titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà kí ó padà síbi ìyapa àṣẹ Allāhu kí ó sì kú sínú ìṣìnà àìgbàgbọ́. Onítọ̀ún ni ẹni tí Allāhu pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ nínú ìmọ̀nà. Irúfẹ́ ẹni yìí l’ó wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀ wọn yóò yọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Mo jẹ; mo mu; mo sùn; mo jí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ”. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’” Wọn yó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yòókù tí ó la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ẹ̀dá. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “wa yuthbit”. tí Allāhu yóò pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ sì l’ó wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀ àwọn āyah kan sì ń bẹ tí Allāhu kò níí pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ l’ó sì wà ní abẹ́ “wa yuthbit”. méjèèjì ti wà nínú kádàrá ẹ̀dá tí ó wà nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àti pé kò sí ẹ̀dá t’ó nímọ̀ èwo nínú àwọn oore ayé àti tọ̀run l’ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ nípasẹ̀ àdúà. Èyí jẹ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ní abala kan. Ó tún jẹ́ ọlá fún àdúà ṣíṣe lábala kan nítorí pé oore àdúà ọ̀tọ̀ oore ẹ̀bùn Ọlọ́hun ọ̀tọ̀. Nítorí náà

[40] Ó ṣeé ṣe kí Á fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí Á ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), iṣẹ́-jíjẹ́ nìkan ni ojúṣe tìrẹ, ìṣírò-iṣẹ́ sì ni tiWa

[41] Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọ inú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn)? Allāhu l’Ó ń ṣe ìdájọ́. Kò sí ẹnì kan tí ó lè dá ìdájọ́ Rẹ̀ padà (fún Un). Òun sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́

[42] Dájúdájú àwọn t’ó ṣíwájú wọn déte. Ti Allāhu sì ni gbogbo ète pátápátá. Ó mọ ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ń ṣe níṣẹ́. Àti pé àwọn aláìgbàgbọ́ ń bọ̀ wá mọ ẹni tí àtubọ̀tán Ilé (rere) wà fún

[43] Àwọn aláìgbàgbọ́ ń wí pé: “Ìwọ kì í ṣe Òjíṣẹ́.” Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹni tí ìmọ̀ Tírà ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”

Ibrāhīmù

Surah 14

[1] ’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà kan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè mú àwọn ènìyàn kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa wọn. (Wọn yó sì bọ́) sí ọ̀nà Alágbára, Ọlọ́pẹ́ (tí ọpẹ́ tọ́ sí)

[2] Allāhu, Ẹni tí Ó ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ègbé ni fún àwọn aláìgbàgbọ́ níbi ìyà líle

[3] Àwọn t’ó ń fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju tọ̀run, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́; àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà t’ó jìnnà

[4] A ò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi pẹ̀lú èdè ìjọ rẹ̀1 nítorí kí ó lè ṣàlàyé (ẹ̀sìn) fún wọn. Nígbà náà, Allāhu yóò ṣi ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà; Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[5] A kúkú fi àwọn āyah Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ pé: “Mú ìjọ rẹ kúrò láti inú àwọn òkùnkùn bọ́ sínú ìmólẹ̀. Kí o sì rán wọn létí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu (lórí wọn).” Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́

[6] (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé ẹ rántí ìkẹ́ Allāhu lórí yín nígbà tí Ó gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín; wọ́n ń dúnńbú àwọn ọmọkùnrin yín, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín

[7] (Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa Ẹlẹ́dàá yín sọ ọ́ di mímọ̀ (fun yín pé): "Dájúdájú tí ẹ bá dúpẹ́, Èmi yóò ṣàlékún fun yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣàìmoore, dájúdájú ìyà Mi mà le

[8] (Ànábì) Mūsā sọ pé: "Tí ẹ bá ṣàìmoore, ẹ̀yin àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́

[9] Ṣé ìró àwọn t’ó ṣíwájú yín kò tí ì dé ba yín ni? Ìjọ (Ànábì) Nūh, ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd àti àwọn t’ó wá lẹ́yìn wọn; kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Allāhu. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nígbà náà, wọ́n ti ọwọ́ wọn bọ ẹnu wọn (ní ti ìbínú), wọ́n sì wí pé: "Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú n̄ǹkan tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́. Àti pé dájúdájú àwa wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí

[10] Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ pé: “Ṣé iyèméjì kan ń bẹ níbi (bíbẹ) Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ó ń pè yín nítorí kí Ó lè forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín àti nítorí kí Ó lè lọ yín lára di gbèdéke àkókò kan.” Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan tayọ abara bí irú wa. Ẹ̀yin sì fẹ́ ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún. Nítorí náà, ẹ fún wa ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.”

[11] Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sọ fún wọn pé: “Àwa kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú yín. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti fun yín ní ẹ̀rí kan àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé, Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé

[12] Kí ni ó máa ṣe wá tí a ò níí gbáralé Allāhu, Ó kúkú ti fi àwọn ọ̀nà wa mọ̀ wá. Dájúdájú a máa ṣe sùúrù lórí ohun tí ẹ bá fi kó ìnira bá wa. Allāhu sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.”

[13] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn Òjíṣẹ́ wọn pé: “Dájúdájú àwa yóò le yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa tàbí kí ẹ kúkú padà sínú ẹ̀sìn wa.” Nígbà náà, Olúwa wọn fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn pé: “Dájúdájú A máa pa àwọn alábòsí run

[14] Dájúdájú A sì máa fun yín ní ibùgbé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn. ” Ìyẹn wà fún ẹni tí ó bá páyà ìdúró (níwájú) Mi, tí ó tún páyà ìlérí Mi

[15] Wọ́n sì tọrọ àrànṣe (Allāhu lórí ìjọ wọn). Gbogbo aláfojúdi, olóríkunkun sì pàdánù

[16] Iná Jahanamọ ń bẹ lẹ́yìn (ìparun) rẹ̀; A ó sì máa fún un ní omi àwọyúnwẹ̀jẹ̀ mu

[17] Ó máa sáré mu ún díẹ̀díẹ̀, kò sì níí fẹ́ẹ̀ lè gbé e mì. (Ìnira) ikú yó sì máa yọ sí i ní gbogbo àyè, síbẹ̀ kò níí kú. Ìyà t’ó nípọn tún wà fún un lẹ́yìn rẹ̀

[18] Àfiwé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn: àwọn iṣẹ́ wọn dà bí eérú tí atẹ́gùn fẹ́ dànù pátápátá ní ọjọ́ ìjì atẹ́gùn. Wọn kò ní agbára kan lórí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ìyẹn ni ìṣìnà t’ó jìnnà

[19] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo? Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá

[20] Ìyẹn kò sì lè dá Allāhu lágara

[21] Gbogbo ẹ̀dá sì máa jáde sọ́dọ̀ Allāhu (lọ́jọ́ Àjíǹde). Nígbà náà, àwọn aláìlágbára yóò wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé n̄ǹkan kan kúrò fún wa nínú ìyà Allāhu?” Wọn yóò wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tọ́ wa sọ́nà ni, àwa ìbá tọ yín sọ́nà. Bákan náà sì ni fún wa, yálà a káyà sókè tàbí a ṣàtẹ̀mọ́ra (ìyà); kò sí ibùsásí kan fún wa.”

[22] Èṣù yó sì wí nígbà tí A bá ṣèdájọ́ (ẹ̀dá) tán, pé: “Dájúdájú Allāhu ṣe àdéhùn fun yín ní àdéhùn òdodo. Èmi náà ṣe àdéhùn fun yín. Mo sì yapa àdéhùn tí mo ṣe fun yín. Èmi kò sì ní agbára kan lórí yín bí kò ṣe pé mo pè yín ẹ sì jẹ́pè mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe bú mi; ara yín ni kí ẹ bú. Èmi kò lè ràn yín lọ́wọ́ (níbi ìyà), Ẹ̀yin náà kò sì lè ràn mí lọ́wọ́ (níbi ìyà). Dájúdájú èmi ti lòdì sí ohun tí ẹ fi sọ mí di akẹgbẹ́ Allāhu ṣíwájú.” Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn

[23] Wọ́n sì máa mú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni ‘àlàáfíà’

[24] Ṣé o ò rí bí Allāhu ti ṣàkàwé ọ̀rọ̀ dáadáa pẹ̀lú igi dáadáa, tí gbòǹgbò rẹ̀ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin, tí ẹka rẹ̀ sì wà nínú sánmọ̀

[25] tó sì ń so èso (jíjẹ) rẹ̀ ní gbogbo ìgbà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀? Allāhu ń fún àwọn ènìyàn ní àwọn àkàwé nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[26] Àkàwé ọ̀rọ̀ tí kò dára sì dà bí igi tí kò dára, tí wọ́n fà tu láti òkè lórí ilẹ̀, tí kò sì ní àyè kan lórí ilẹ̀

[27] Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ó sì máa ṣi àwọn alábòsí lọ́nà. Àti pé Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́

[28] Ṣé o ò rí àwọn t’ó yí ìdẹ̀ra Allāhu padà sí àìgbàgbọ́, tí wọ́n sì mú ìjọ wọn gúnlẹ̀ sí ilé ìparun

[29] Iná Jahanamọ ni wọn yóò gúnlẹ̀ sí; ibùgbé náà sì burú

[30] Wọ́n sọ (àwọn kan di) akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò nínú ẹ̀sìn Rẹ̀. Sọ pé: “Ẹ máa gbádùn ǹsó, nítorí pé dájúdájú àbọ̀ yín ni Iná.”

[31] Sọ fún àwọn ẹrúsìn Mi pé kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò níí sí títà-rírà kan àti yíyan ọ̀rẹ́ kan nínú rẹ̀

[32] Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì fi ń mú àwọn èso jáde; (ó jẹ́) arísìkí fun yín. Ó sì rọ ọkọ̀ ojú-omi fun yín kí ó lè rìn lójú omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Ó tún rọ àwọn odò fun yín

[33] Ó rọ òòrùn àti òṣùpá fun yín, tí méjèèjì ń rìn láì sinmi. Ó tún rọ òru àti ọ̀sán fun yín

[34] Àti pé Ó ń fun yín nínú gbogbo n̄ǹkan tí ẹ tọrọ lọ́dọ̀ Rẹ̀. Tí ẹ bá ṣe òǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú ènìyàn ni alábòsí aláìmoore

[35] (Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: "Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì mú èmi àti àwọn ọmọ mi jìnnà sí jíjọ́sìn fún àwọn òrìṣà

[36] Olúwa mi, dájúdájú àwọn òrìṣà ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ènìyàn sọnù. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé mi, dájúdájú òun ni ẹni mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa mi, dájúdájú Ìwọ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́

[37] Olúwa wa, dájúdájú èmi wá ibùgbé fún àrọ́mọdọ́mọ mi sí ilẹ̀ àfonífojì, ilẹ̀ tí kò ní èso, nítòsí Ilé Rẹ Ọlọ́wọ̀. Olúwa wa, nítorí kí wọ́n lè kírun ni. Nítorí náà, jẹ́ kí ọkàn àwọn ènìyàn fà sọ́dọ̀ wọn. Kí O sì pèsè àwọn èso fún wọn nítorí kí wọ́n lè dúpẹ́ (fún Ọ)

[38] Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O mọ ohun tí à ń fi pamọ́ àti ohun tí à ń ṣe àfihàn rẹ̀. Kò sì sí kiní kan nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀ t’ó pamọ́ fún Allāhu

[39] Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fún mi ní ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ nígbà tí mo ti darúgbó. Dájúdájú, Olúwa mi ni Olùgbọ́ àdúà

[40] Olúwa mi, ṣe èmi àti nínú àrọ́mọdọ́mọ mi ni olùkírun. Olúwa wa, kí O sì gba àdúà mi

[41] Olúwa mi, ṣàforíjìn fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọjọ́ tí ìṣírò-iṣẹ́ yóò ṣẹlẹ̀

[42] Má ṣe lérò pé Allāhu gbàgbé n̄ǹkan tí àwọn alábòsí ń ṣe níṣẹ́. Ó kàn ń lọ́ wọn lára dí ọjọ́ kan tí àwọn ojú yóò yọ síta ràngàndàn

[43] Wọn yóò má sáré (lọ síbi àkójọ fún ìṣírò-iṣẹ́), wọn yóò gbé orí wọn sókè, ìpéǹpéjú wọn kò sì níí padà sọ́dọ̀ wọn, àwọn ọkàn wọn yó sì pa sófo pátápátá (fún ìbẹ̀rù)

[44] Kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, àwọn t’ó ṣàbòsí yó sì wí pé: “Olúwa wa, lọ́ wa lára fún àsìkò díẹ̀ sí i, a máa jẹ́pè Rẹ, a sì máa tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́.” Ṣé ẹ̀yin kò ti búra ṣíwájú pé ẹ̀yin kò níí kúrò nílé ayé ni

[45] Ẹ sì gbé nínú ibùgbé àwọn t’ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Ó sì hàn si yín bí A ti ṣe pẹ̀lú wọn. A tún fun yín ni àwọn àkàwé

[46] Wọ́n kúkú ti dá ète wọn, ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ète wọn wà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé (pẹ̀lú) ète wọn àpáta fẹ́ẹ̀ lè yẹ̀ lulẹ̀

[47] Nítorí náà, má ṣe lérò pé Allāhu yóò yapa àdéhùn Rẹ̀ tí Ó ṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùgbẹ̀san

[48] Ní ọjọ́ tí A máa yí ilẹ̀ ayé padà sì n̄ǹkan mìíràn. (A máa yí) àwọn sánmọ̀ náà (padà. Àwọn ẹ̀dá) sì máa jáde (síwájú) Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí

[49] O sì máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí wọn yóò so wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn sínú sẹ́kẹ́sẹkẹ̀

[50] Òjé Iná ni àwọn èwù wọn. Iná yó sì bo ojú wọn mọ́lẹ̀ bámúbámú

[51] nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́

[52] Èyí ni iṣẹ́-jíjẹ́ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè fi ṣe ìkìlọ̀, kí wọ́n sì lè mọ̀ pé (Allāhu) Òun nìkan ni Ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí, Ọ̀kan ṣoṣo, àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí

Àpáta

Surah 15

[1] ’Alif lām rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur’ān t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá

[2] Ó ṣeé ṣe kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé)

[3] Fi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀

[4] A kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀

[5] Kò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn

[6] Wọ́n wí pé: “Ìwọ tí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún, dájúdájú wèrè ni ẹ́

[7] Kí ni kò jẹ́ kí ìwọ mú àwọn mọlāika wá bá wa, tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo?”

[8] A ò níí sọ mọlāika kalẹ̀ bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Wọn kò sì níí lọ́ wọn lára mọ́ nígbà náà (tí àwọn mọlāika bá sọ̀kalẹ̀)

[9] Dájúdájú Àwa l’A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur’ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀

[10] Dájúdájú ṣíwájú rẹ A ti rán (àwọn Òjíṣẹ́) níṣẹ́ sí àwọn ìjọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́

[11] Òjíṣẹ́ kan kò sì níí dé bá wọn àfi kí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́

[12] Báyẹn ni A ṣe ń fi (àìsàn) sínú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

[13] Wọn kò níí gba Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbọ́; ìṣe (Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá

[14] Tí ó bá jẹ́ pé A ṣí ìlẹ̀kùn kan sílẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀, tí wọn kò sì yé gbabẹ̀ gùnkè lọ (sínú sánmọ̀)

[15] dájúdájú wọ́n á wí pé: “Wọ́n kúkú lo ìṣíjú fún wa ni. Ńṣe ni wọ́n ń dan wá.”

[16] A kúkú fi àwọn ibùsọ̀ (ìràwọ̀) sínú sánmọ̀ (ayé). A sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran

[17] A sì fi ààbò bo ìmísí sánmọ̀ lọ́dọ̀ gbogbo èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀

[18] Àfi (èṣù) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn

[19] Ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀

[20] A ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún

[21] Kò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀

[22] Àti pé A rán atẹ́gùn láti kó ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fun yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀)

[23] Dájúdájú Àwa, Àwa mà l’À ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá)

[24] Àti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn

[25] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

[26] Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà

[27] Àti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín

[28] (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà

[29] Nígbà tí Mo bá ṣe é t’ó gún régé tán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni

[30] Nítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i

[31] Àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ náà

[32] (Allāhu) sọ pé: "’Iblīs, kí l’ó dí ọ lọ́wọ́ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀

[33] Ó wí pé: "Èmi kò níí forí kanlẹ̀ kí abara kan tí O ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà

[34] (Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, jáde kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú, ìwọ ni ẹni-ẹ̀kọ̀

[35] Àti pé, dájúdájú ègún ń bẹ lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san

[36] Ó wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di Ọjọ́ Àjíǹde.”

[37] (Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn tí A óò lọ́ lára

[38] títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ

[39] Ó wí pé: "Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe mí ní ẹni anù, dájúdájú emí yóò ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún wọn lórí ilẹ̀. Dájúdájú èmi yó sì kó gbogbo wọn sínú anù

[40] àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni ẹ̀ṣà nínú wọn

[41] (Allāhu) sọ pé: "(Ìdúróṣinṣin lójú) ọ̀nà tààrà, Ọwọ́ Mi ni èyí wà

[42] Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn, àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú àwọn ẹni anù

[43] Àti pé dájúdájú iná Jahanamọ ni àdéhùn fún gbogbo wọn

[44] Àwọn ojú ọ̀nà méje ń bẹ fún (iná). Àtúnpín tún wà fún ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan

[45] Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn odò (t’ó ń ṣàn nísàlẹ̀ rẹ̀)

[46] (A máa sọ pé): “Ẹ wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ní olùfàyàbalẹ̀.”

[47] A sì máa yọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn t’ó jẹ́ inúnibíni kúrò; (wọn yóò di) ọmọ-ìyá (ara wọn. Wọn yóò wà) lórí ibùsùn, tí wọn yóò kọjú síra wọn

[48] Wàhálà kan kò níí bá wọn nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀

[49] Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[50] Àti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[51] Fún wọn ní ìró nípa àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm

[52] (Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà”. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa.”

[53] Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin onímímọ̀ kan

[54] Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná

[55] Wọ́n sọ pé: “À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná.”

[56] Ó sọ pé: “Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà.”

[57] Ó sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”

[58] Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni

[59] Àfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá

[60] Àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn t’ó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun

[61] Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt

[62] (Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn.”

[63] Wọ́n sọ pé: “Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀

[64] A mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa

[65] Nítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fun yín

[66] A sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́

[67] Àwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀

[68] (Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí

[69] Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi

[70] Wọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?”

[71] Ó sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe.”

[72] (Allāhu sọ pé): “Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra; dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìdààmú ọpọlọ, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà.”

[73] Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn

[74] A sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí

[75] Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye

[76] Dájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀)

[77] Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[78] Àwọn ará ’Aekah náà jẹ́ alábòsí

[79] A sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì l’ó kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀)

[80] Dájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́

[81] A sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀

[82] Wọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta

[83] Ohùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́

[84] Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà)

[85] A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò t’ó rẹwà

[86] Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀

[87] Dájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur’ān t’ó tóbi

[88] Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé lóríṣiríṣi fún àwọn kan nínú wọn. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[89] Kí o sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”

[90] Gẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn t’ó ń pín òdodo mọ́ irọ́

[91] àwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān di ìpínkúpìn-ín

[92] Olúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè

[93] nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[94] Nítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ

[95] Dájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́

[96] àwọn t’ó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀

[97] Àwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ

[98] Nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ. Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un)

[99] Jọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ

Oyìn

Surah 16

[1] Àṣẹ Allāhu dé tán. Ẹ ma wulẹ̀ wá a pẹ̀lú ìkánjú. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[2] (Allāhu) ń fi àṣẹ Rẹ̀ sọ mọlāika (Jibrīl) kalẹ̀ láti máa mú ìmísí wá díẹ̀díẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ (bẹ́ẹ̀ fún) nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ẹ lè fi ṣe ìkìlọ̀ pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.”

[3] Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[4] Ó dá ènìyàn láti inú àtọ̀. (Ènìyàn) sì di olùjiyàn pọ́nńbélé (nípa Àjíǹde)

[5] Àwọn ẹran-ọ̀sìn, Ó ṣẹ̀dá wọn. Aṣọ òtútù àti àwọn àǹfààní (mìíràn) ń bẹ fun yín lára wọn. Àti pé ẹ̀ ń jẹ nínú wọn

[6] Ọ̀ṣọ́ tún ń bẹ fun yín lára wọn nígbà tí ẹ bá ń dà wọ́n lọ (sí ilé wọn) àti nígbà tí ẹ bá ń kó wọn jáde lọ jẹko

[7] Wọ́n sì ń ru àwọn ẹrù yín t’ó wúwo lọ sí ìlú kan tí ẹ ò lè dé àfi pẹ̀lú wàhálà ẹ̀mí. Dájúdájú Olúwa yín mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́

[8] (Ó ṣẹ̀dá) ẹṣin, ìbaaka àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ nítorí kí ẹ lè gùn wọ́n. (Wọ́n tún jẹ́) ọ̀ṣọ́. Ó tún ń ṣẹ̀dá ohun tí ẹ ò mọ̀

[9] Allāhu l’Ó ń ṣàlàyé (’Islām) ọ̀nà tààrà. Àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wíwọ́ tún wà (lọ́tọ̀) . Tí Ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìbá tọ́ gbogbo yín sí ọ̀nà (ẹ̀sìn ’Islām)

[10] Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Mímu wà fun yín nínú rẹ̀. Igi ewéko tún ń wù jáde láti inú rẹ̀. Ẹ sì ń fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn

[11] (Allāhu) tún ń fi (omi yìí) hu àwọn irúgbìn, igi òróró zaetūn, igi dàbínù, igi àjàrà àti gbogbo àwọn èso (yòókù) jáde fun yín. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀

[12] Ó rọ òru, ọ̀sán, òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fun yín pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè

[13] Àti ohun tí Ó tún ṣẹ̀dá rẹ̀ fun yín lórí ilẹ̀, tí àwọn àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń lo ìrántí

[14] Òun ni Ẹni tí Ó rọ agbami odò nítorí kí ẹ lè jẹ ẹran (ẹja) tútù àti nítorí kí ẹ lè mú n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ tí ẹ óò máa wọ̀ sára jáde láti inú (odò), - ó sì máa rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí yóò máa la ojú omi kọjá lọ bọ̀ – àti nítorí kí ẹ lè wá nínú àwọn àjùlọ oore Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu)

[15] Ó sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sórí ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ yín lẹ́sẹ̀ àti àwọn odò àti àwọn ojú-ọ̀nà nítorí kí ẹ lè dá ojú ọ̀nà mọ̀

[16] àti àwọn àmì òpópónà (fún ìtọ́sọ́nà ìrìn ọ̀sán). Wọ́n tún ń fi ìràwọ̀ dá ojú ọ̀nà mọ̀ (lálẹ́)

[17] Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá dà bí ẹni tí kò dá ẹ̀dá bí? Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni

[18] Tí ẹ bá ṣòǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú Allāhu mà ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́

[19] Àti pé Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀

[20] Àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu; wọn kò lè dá kiní kan. Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá wọn

[21] Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè. Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò gbé wọn dìde. wọn kì í ṣe alààyè.” kò sọ ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ohun t’ó ti ṣẹlẹ̀. Ṣebí àwọn mọlāika kan wà lára n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣé òkú ni àwọn mọlaika náà ni tàbí alààyè? A ò kúkú tí ì gbọ́ ikú mọlaika kan kan rí. Bákan náà aṣ-Ṣatọ̄n ar-Rọjīm jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún. Ṣé òkú ni Ṣaetọ̄n náà ni tàbí alààyè? Rárá bí Allāhu ṣe fẹ́.” Kò wá sí ẹ̀rí tààrà kan kan t’ó fi rinlẹ̀ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú bí kò ṣe āyah onípọ́nna èyí tí a ti ṣe àlàyé lórí rẹ̀ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-’Imrọ̄n 3:55. Dípò kí á rí āyah kan tàbí hadīth kan tààrà lórí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) hadīth t’ó ń fi ìpadàbọ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ l’à ń rí. Ẹni tí kò ì kú l’ó sì lè padà wá sílé ayé. ” nínú āyah náà kì í ṣe ìtúmọ̀ àdámọ́. Ìdí ni pé ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀

[22] Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àmọ́ àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni ọkàn wọn takò ó, tí wọ́n sì ń ṣègbéraga

[23] Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga

[24] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ni.”

[25] (Wọ́n sọ bẹ́ẹ̀) nítorí kí wọ́n lè ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ní pípé pérépéré ní Ọjọ́ Àjíǹde àti (nítorí kí wọ́n lè rù) nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n ń ṣì lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Gbọ́, ohun tí wọn yóò rù ní ẹ̀ṣẹ̀, ó burú

[26] Àwọn t’ó ṣíwájú wọn kúkú déte. Allāhu sì da ilé wọn wó láti ìpìlẹ̀. Òrùlé sì wó lù wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn. Àti pé ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura

[27] Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde (Allāhu) yóò yẹpẹrẹ wọn. Ó sì máa sọ pé: “Ibo ni àwọn (tí ẹ sọ di) akẹgbẹ́ Mi wà, àwọn tí ẹ tì torí wọn yapa (Mi)?” Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ẹ̀sìn yó sì sọ pé: “Dájúdájú àbùkù àti aburú ọjọ́ òní wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

[28] (Àwọn ni) àwọn tí mọlāika ń pa nígbà tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn lọ́wọ́. Ní àsìkò yìí ni wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (wọ́n sì wí pé): “Àwa kò ṣe iṣẹ́ aburú kan kan.” Rárá (ẹ ṣiṣẹ́ aburú)! Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[29] Nítorí náà, ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà Iná lọ, olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú

[30] Wọ́n sọ fún àwọn t’ó bẹ̀rù (Allāhu) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Rere ni.” Rere ti wà fún àwọn t’ó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn lóore jùlọ. Àti pé dájúdájú ilé àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) dára

[31] Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń san ẹ̀san rere fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[32] Àwọn tí mọlāika ń pa, nígbà tí wọ́n ń ṣe rere lọ́wọ́, (àwọn mọlāika) ń sọ pé: “Àlàáfíà fun yín. Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

[33] Ṣé wọ́n ń retí ohun kan yàtọ̀ sí pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí àṣẹ Olúwa rẹ dé? Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ti ṣe. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí

[34] Nítorí náà, àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po

[35] Àwọn tí wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́ yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fẹ́ ni àwa ìbá tí jọ́sìn fún kiní kan lẹ́yìn Rẹ̀, àwa àti àwọn bàbá wa. Bákàn náà, àwa ìbá tí ṣe kiní kan ní èèwọ̀ lẹ́yìn Rẹ̀.” Báyẹn ni àwọn t’ó ṣíwájú wọn ti ṣe. Ǹjẹ́ ojúṣe kan wà fún àwọn Òjíṣẹ́ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé

[36] Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà.” Nítorí náà, ó wà nínú wọn, ẹni tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Ó sì wà nínú wọn, ẹni tí ìṣìnà kò lé lórí. Nítorí náà, ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ sì wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn t’ó pé àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́ ṣe rí

[37] Tí o bá ń ṣojú kòkòrò sí ìmọ̀nà wọn, ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, dájúdájú kò níí fi mọ̀nà, kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan kan fún wọn

[38] Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: “Allāhu kò níí gbé ẹni tí ó kú dìde.” Kò rí bẹ́ẹ̀, (àjíǹde jẹ́) àdéhùn lọ́dọ̀ Allāhu. Òdodo sì ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò mọ̀

[39] (Allāhu yóò gbé ẹ̀dá dìde) nítorí kí Ó lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí fún wọn àti nítorí kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lè mọ̀ pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ òpùrọ́

[40] Ọ̀rọ̀ Wa fún kiní kan nígbà tí A bá gbèrò rẹ̀ ni pé, A máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.”

[41] Àwọn t’ó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ti Allāhu, lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti ṣàbòsí sí wọn, dájúdájú Àwa yóò wá ibùgbé rere fún wọn. Ẹ̀san Ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé (àwọn tí kò ṣe hijrah) mọ̀

[42] (Àwọn ni) àwọn t’ó ṣe sùúrù, wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn

[43] A ò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀. kì í ṣe àwọn sūfī. Ìdí ni pé okùnfà āyah méjèèjì yìí ni pé

[44] (A fi) àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú àti ìpín-ìpín Tírà (rán wọn níṣẹ́). Àti pé A sọ tírà Ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ nítorí kí o lè ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀

[45] Ṣé àwọn t’ó dá ète aburú fi ọkàn balẹ̀ pé Allāhu kò lè mú ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ni, tàbí pé ìyà kò lè dé bá wọn láti àyè tí wọn kò ti níí fura

[46] Tàbí (Allāhu) kò lè gbá wọn mú lórí ìrìnkè-rindò wọn ni? Wọn kò sì níí mórí bọ́

[47] Tàbí (Allāhu) kò lè máa gbá wọn mú díẹ̀díẹ̀ ni? Nítorí náà, dájúdájú Olúwa yin má ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́

[48] Àti pé ṣé wọn kò rí gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀, tí òòji rẹ̀ ń padà yọ láti ọ̀tún àti òsì ní olùforíkanlẹ̀ fún Allāhu; tí wọ́n sì ń yẹpẹrẹ ara wọn (fún Un)

[49] Allāhu sì ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ní n̄ǹkan abẹ̀mí àti àwọn mọlāika ń forí kanlẹ̀ fún. Wọn kò sì ṣègbéraga

[50] Wọ́n ń páyà Olúwa wọn t’Ó ń bẹ lókè wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí À ń pa láṣẹ fún wọn

[51] Allāhu sọ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ọlọ́hun méjì. Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí ìjọ́sìn tọ́ sí. Nítorí náà, Èmi (nìkan) ni kí ẹ bẹ̀rù.”

[52] TiRẹ̀ sì ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. TiRẹ̀ sì ni ẹ̀sìn títí láéláé Nítorí náà, ṣé (n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí Allāhu ni ẹ̀yin yóò máa bẹ̀rù ni

[53] Ohunkóhun tí ẹ ní nínú ìdẹ̀ra, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Lẹ́yìn náà, tí ọwọ́ ìnira bá tẹ̀ yín, Òun ni kí ẹ máa pè (fún ìdáǹdè)

[54] Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá sì mú ìnira náà kúrò fun yín tán, nígbà náà ni apá kan nínú yín yó sì máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn

[55] nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn. Nítorí náà, ẹ máa gbádùn ǹsó. Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀

[56] Wọ́n ń fi ìpín kan nínú ohun tí A pèsè fún wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọn kò mọ̀. Mo fi Allāhu búra, dájúdájú wọn yóò bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń dá ní àdápa irọ́

[57] Wọ́n tún ń fi (bíbí) àwọn ọmọbìnrin lélẹ̀ fún Allāhu - Mímọ́ ni fún Un (kò bímọ). – Wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń fẹ́ lélẹ̀ fún tiwọn

[58] Nígbà tí wọ́n bá fún ọ̀kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú (pé ó bí) ọmọbìnrin, ojú rẹ̀ yóò ṣókùnkùn, ó sì máa kún fún ìbànújẹ́

[59] Ó sì máa fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn nítorí ìró aburú tí wọ́n fún un. Ṣé ó máa gbà á ní n̄ǹkan àbùkù ni tàbí ó máa bò ó mọ́lẹ̀ láàyè? Ẹ gbọ́, ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú

[60] Ti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ni àkàwé aburú. Ti Allāhu sì ni àkàwé t’ó ga jùlọ. Àti pé Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[61] Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń gbá àwọn ènìyàn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn, ìbá tí ṣẹ́ abẹ̀mí kan kan kù sórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú di ìgbà kan, wọn kò sì níí fà á sẹ́yìn.”

[62] Wọ́n ń fi (ọmọbìnrin) n̄ǹkan tí wọn kórira lélẹ̀ fún Allāhu. Ahọ́n wọn sì ń ròyìn irọ́ pé dájúdájú rere ni tàwọn. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Iná ni tiwọn. Àti pé dájúdájú wọ́n máa pa wọ́n tì sínú rẹ̀ ni

[63] Mo fi Allāhu búra, dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. Nígbà náà, Èṣù ṣe iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn; òun sì ni ọ̀rẹ́ wọn lónìí. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[64] A kò sọ Tírà náà kalẹ̀ fún ọ bí kò ṣe pé kí o lè ṣàlàyé fún wọn ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí; ó sì jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo

[65] Allāhu l’Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó sì ń fi jí ilẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti kú. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀ (òdodo)

[66] Dájúdájú àríwòye wà fun yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn, tí À ń fun yín mu nínú n̄ǹkan t’ó wà nínú rẹ̀, (èyí) tí ó ń jáde wá láti ààrin bọ́tọ inú agbẹ̀du àti ẹ̀jẹ̀. (Ó sì ń di) wàrà mímọ́ t’ó ń lọ tìnrín ní ọ̀fun àwọn t’ó ń mu ún

[67] Àti pé láti ara àwọn èso dàbínù àti èso àjàrà ni ẹ ti ń ṣe ọtí àti ohun àmú-ṣọrọ̀ t’ó dára. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè

[68] Olúwa rẹ sì fi mọ kòkòrò oyin pé: "Mu ilé sínú àpáta, igi àti ohun tí (àwọn ènìyàn) mọ ga

[69] Lẹ́yìn náà, jẹ lára gbogbo èso, kí o sì tọ àwọn ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ìtẹríba." Ohun mímu tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn yóò máa jáde láti inú kòkòrò oyin. Ìwòsàn ni fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀

[70] Allāhu l’Ó ṣẹ̀dá yín. Lẹ́yìn náà, Ó ń gba ẹ̀mí yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá padà sí ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alágbára

[71] Allāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, kí wọ́n fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, kí wọ́n sì jọ pín in ní dọ́gbadọ́gba! Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò

[72] Àti pé Allāhu ṣe àwọn ìyàwó fun yín láti ara yín. Ó fun yín ní àwọn ọmọ àti ọmọọmọ láti ara àwọn ìyàwó yín. Ó sì pèsè arísìkí fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ṣé irọ́ (ìyẹn, òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, wọn yó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ìdẹ̀ra Allāhu

[73] Dípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò ní ìkápá arísìkí kan kan fún wọn nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀; wọn kò sì lágbára (láti ṣe n̄ǹkan kan)

[74] Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn àkàwé náà lélẹ̀ nípa Allāhu. Dájúdájú Allāhu nímọ̀; ẹ̀yin kò sì nímọ̀

[75] Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí t’ó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[76] Allāhu tún fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ọkùnrin méjì kan, tí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ odi, tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe, tí ó tún jẹ́ wàhálà fún ọ̀gá rẹ̀ (nítorí pé) ibikíbi tí ó bá rán an lọ, kò níí mú oore kan bọ̀ (fún un láti ibẹ̀). Ṣé ó dọ́gba pẹ̀lú ẹni tí Ó ń pàṣẹ ṣíṣe ẹ̀tọ́, tí ó sì wà lójú ọ̀nà tààrà

[77] Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀rọ̀ Àkókò náà kò kúkú tayọ ìṣẹ́jú tàbí kí ó tún súnmọ́ julọ. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[78] Allāhu l’Ó mu yín jáde láti inú ikùn àwọn ìyá yín nígbà tí ẹ̀yin kò tí ì dá n̄ǹkan kan mọ̀. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)

[79] Ṣé wọn kò wòye sí àwọn ẹyẹ tí A rọ̀ (fún fífò) nínú òfurufú (lábẹ́) sánmọ̀? Kò sí ẹni t’ó ń mú wọn dúró (sínú òfurufú) bí kò ṣe Allāhu. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo

[80] Allāhu ṣe ibùsinmi fun yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan t’ó fúyẹ́ fun yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn, irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀. aṣọ èyí tí wọ́n bá fi irun àgùtàn hún máa ń jẹ́ aṣọ t’ó rọjú jùlọ ní rírà. Nítorí èyí aṣọ irun àgùtàn jẹ́ aṣọ àwọn mẹ̀kúnnù. Àwọn olówó kì í sì fẹ́ rà á fún wíwọ̀ sọ́rùn nítorí pé olùfọkànsìn ẹni ẹ̀ṣà òǹpèrò kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àáfà onibidiah wọ̀nyẹn bá tún bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ ara rẹ̀ pèrò dípò lílo orúkọ àgbélẹ̀rọ tí wọ́n dìjọ ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀. Nígbà náà ni ayé wọn bá di ìlànà / tọrīkọ “at-tasọwuffu al-kọ̄diriyyah” tí ọkùnrin kan kò bá ti rí iṣẹ́ halāl ṣe ní iṣẹ́ òòjọ́ ó máa di “ṣééù”

[81] Allāhu ṣe àwọn ibòji fun yín láti ara n̄ǹkan tí Ó dá. Ó ṣe àwọn ibùgbé fun yín láti ara àwọn àpáta. Ó tún ṣe àwọn aṣọ fun yín t’ó ń dáàbò bò yín lọ́wọ́ ooru àti àwọn aṣọ t’ó ń dáàbò bò yín lójú ogun yín. Báyẹn l’Ó ṣe ń pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ le yín lórí nítorí kí ẹ lè jẹ́ mùsùlùmí

[82] Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé lojúṣe tìrẹ

[83] Wọ́n mọ ìdẹ̀ra Allāhu, lẹ́yìn náà wọ́n ń takò ó. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni aláìmoore

[84] (Rántí) ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí kan dìde nínú gbogbo ìjọ (àwọn Ànábì), lẹ́yìn náà, A ò níí yọ̀ǹda (àròyé ṣíṣe) fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti padà ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu

[85] Nígbà tí àwọn t’ó ṣàbòsí bá rí Ìyà, nígbà náà, A ò níí ṣe ìyà wọn ní fífúyẹ́, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná)

[86] Nígbà tí àwọn t’ó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ bá rí àwọn òrìṣà wọn, wọ́n á wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí ni àwọn òrìṣà wa tí à ń pè lẹ́yìn Rẹ.” Nígbà náà (àwọn òrìṣà) yóò ju ọ̀rọ̀ náà padà sí wọ́n pé: “Dájúdájú òpùrọ́ mà ni ẹ̀yin.”

[87] Wọ́n sì máa jura wọn sílẹ̀ fún Allāhu ní ọjọ́ yẹn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ yó sì di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́

[88] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, A ó ṣe àlékún ìyà lórí ìyà fún wọn nítorí pé wọ́n ń ṣèbàjẹ́

[89] (Rántí) Ọjọ́ tí A óò gbé ẹlẹ́rìí dìde fún ìjọ kọ̀ọ̀kan láààrin ara wọn, A sì máa mú ìwọ wá ní ẹlẹ́rìí fún àwọn wọ̀nyí. A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan, ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí

[90] Dájúdájú Allāhu ń pàṣẹ ṣíṣe déédé, ṣíṣe rere àti fífún ẹbí (ní n̄ǹkan). Ó sì ń kọ ìwà ìbàjẹ́, ohun burúkú àti rúkèrúdò. Ó ń ṣe wáàsí fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí

[91] Kí ẹ sì mú àdéhùn Allāhu ṣẹ nígbà tí ẹ bá ṣe àdéhùn. Ẹ má ṣe tú ìbúra lẹ́yìn ìfirinlẹ̀ rẹ̀. Ẹ sì kúkú ti fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí lórí ara yín. Dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[92] Kí ẹ sì má ṣe dà bí (obìnrin) èyí tí ó tú òwú dídì rẹ̀ palẹ̀ lẹ́yìn tí ó tí dì í le. Ńṣe ni ẹ̀ ń lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín nítorí pé ìran kan pọ̀ ju ìran kan lọ. Dájúdájú Allāhu ń dan yín wò pẹ̀lú rẹ̀ ni. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde Ó kúkú máa ṣàlàyé fun yín ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí

[93] Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe yín ní ìjọ kan ṣoṣo (sínú ’Islām), ṣùgbọ́n Ó ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Dájúdájú Wọ́n máa bi yín léèrè nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[94] Ẹ má ṣe lo ìbúra yín fún ẹ̀tàn láààrin ara yín, nítorí kí ẹsẹ̀ yín má baà yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìdúróṣinṣin rẹ̀, àti nítorí kí ẹ má baà tọ́ ìyà burúkú wò nípa bí ẹ ṣe ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Ìyà ńlá yó sì wà fun yín

[95] Ẹ má ṣe ta àdéhùn Allāhu ní owó pọ́ọ́kú. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu, ó lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀

[96] Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ yín máa tán. Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì máa wà títí láéláé. Dájúdájú A sì máa fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san àwọn t’ó ṣe sùúrù lẹ́san wọn

[97] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé t’ó dára. Dájúdájú A ó sì fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn

[98] Nígbà tí o bá (fẹ́) ké al-Ƙur’ān, sá di Allāhu níbi (aburú) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀

[99] Dájúdájú kò sí agbára kan fún un lórí àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn

[100] Ẹni t’ó lágbára lórí rẹ̀ ni àwọn t’ó ń mú un ní ọ̀rẹ́ àti àwọn t’ó sọ ọ́ di akẹgbẹ́ Allāhu

[101] Nígbà tí A bá pààrọ̀ āyah kan sí àyè āyah kan, Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun t’Ó ń sọ̀kalẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ìwọ kàn jẹ́ aládapa irọ́ ni.” Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀

[102] Sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ (mọlāika Jibrīl) l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní ti òdodo nítorí kí ó lè mú ẹsẹ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo rinlẹ̀. (Kí ó sì lè jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí

[103] A sì kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: “Ṣebí abara kan l’ó ń kọ́ ọ (ní al-Ƙur’ān).” Èdè ẹni tí wọ́n ń yẹ̀ sí (tí wọ́n ń tọ́ka sí pé ó ń kọ́ ọ) kì í ṣe elédè Lárúbáwá. Èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé sì ni (al-Ƙur’ān) yìí

[104] Dájúdájú àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, Allāhu kò níí tọ́ wọn sọ́nà. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[105] Àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu l’ó ń dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu). Àwọn wọ̀nyẹn sì ni òpùrọ́

[106] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu lẹ́yìn ìgbàgbọ́ rẹ̀, yàtọ̀ sí ẹni tí wọ́n jẹ nípá, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí àìgbàgbọ́ bá tẹ́ lọ́rùn, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ń bẹ lórí wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn

[107] Ìyẹn nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ìṣẹ̀mí ayé ju ọ̀run. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́

[108] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti fi èdídí bo ọkàn wọn, ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni afọ́núfọ́ra

[109] Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú àwọn ni olófò ní ọ̀run

[110] Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn t’ó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn aláìgbàgbọ́ ti kó ìfòòró bá wọn, lẹ́yìn náà, tí wọ́n jagun ẹ̀sìn, tí wọ́n sì ṣe sùúrù - dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run (fún wọn) lẹ́yìn (ìfòòró tí wọ́n rí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́)

[111] (Rántí) Ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò dé láti du orí ara rẹ̀. A ó sì san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́; wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[112] Allāhu fi àkàwé lélẹ̀ nípa ìlú kan, tí ó jẹ́ (ìlú) ààbò àti ìfàyàbalẹ̀, tí arísìkí rẹ̀ ń tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ ní púpọ̀ ní gbogbo àyè. Àmọ́ (wọ́n) ṣe àìmoore sí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ìyà ebi àti ìpáyà tọ́ wò nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[113] Òjíṣẹ́ kúkú ti dé bá wọn láààrin ara wọn. Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ọwọ́ ìyà bà wọ́n. Alábòsí sì ni wọ́n

[114] Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fun yín ní n̄ǹkan ẹ̀tọ́, t’ó dára. Kí ẹ sì dúpẹ́ oore Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún

[115] Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fun yín ni ẹran òkúǹbete, ẹ̀jẹ̀, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ t’ó yàtọ́ sí “Allāhu”. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fi ìnira ebi kan, yàtọ̀ sí ẹni t’ó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-àlà, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[116] Ẹ má ṣe sọ nípa ohun tí ahọ́n yín ròyìn ní irọ́ pé: “Èyí ni ẹ̀tọ́, èyí sì ni èèwọ̀” nítorí kí ẹ lè dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Dájúdájú àwọn t’ó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè

[117] Ìgbádùn ayé bín-íntín (lè wà fún wọn, àmọ́) ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn (ní ọ̀run)

[118] Àti pé A ṣe ohun tí A sọ fún ọ ṣíwájú ní èèwọ̀ fún àwọn t’ó di yẹhudi. A ò sì ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn

[119] Lẹ́yìn náà, dájúdájú Olúwa rẹ - nípa àwọn t’ó ṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe lẹ́yìn rẹ̀ dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[120] Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jẹ́ aṣíwájú-àwòkọ́ṣe-rere, olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì jẹ́ ara àwọn ọ̀ṣẹbọ

[121] Ó máa ń dúpẹ́ àwọn ìdẹ̀ra Allāhu. Allāhu ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà (’Islām)

[122] A ṣe ohun rere fún un nílé ayé. Àti pé ní ọ̀run dájúdájú ó máa wà nínú àwọn ẹni rere

[123] Lẹ́yìn náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ pé kí o tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn. Kò sì wà lára àwọn ọ̀ṣẹbọ

[124] Àwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn t’ó yapa ẹnu nípa rẹ̀. Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí

[125] Pèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì s.a.w.) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí t’ó dára jùlọ. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀ (’Islām). Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà (àwọn mùsùlùmí)

[126] Tí ẹ (bá fẹ́) gbẹ̀san (ìyà), ẹ gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ yín. Dájúdájú tí ẹ bá sì ṣe sùúrù, ó mà sì lóore jùlọ fún àwọn onísùúrù

[127] Ṣe sùúrù. Ìwọ kò sì lè rí sùúrù ṣe àfi pẹ̀lú (ìrànlọ́wọ́) Allāhu. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì ṣe wà nínú ìbànújẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ń dá ní ète

[128] Dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) àti àwọn t’ó ń ṣe rere

Ìrìn-àjò Òru

Surah 17

[1] Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran

[2] A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì ṣe é ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (A sì sọ) pé: “Ẹ má ṣe mú aláàbò kan lẹ́yìn Mi.”

[3] (Ẹ jẹ́) àrọ́mọdọ́mọ àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh. Dájúdájú (Nūh) jẹ́ ẹrúsìn, olùdúpẹ́

[4] A sì fi mọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nínú Tírà pé: “Dájúdájú ẹ máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà mejì. Dájúdájú ẹ tún máa ṣègbéraga t’ó tóbi.”

[5] Nítorí náà, nígbà tí àdéhùn fún àkọ́kọ́ nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀, A máa gbé àwọn ẹrúsìn Wa kan, tí wọ́n lágbára gan-an, dìde si yín. Wọn yóò dá rògbòdìyàn sílẹ̀ láààrin ìlú (yín). Ó jẹ́ àdéhùn kan tí A máa mú ṣẹ

[6] Lẹ́yìn náà, A dá ìṣẹ́gun lórí wọn padà fun yín. A sì fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ ṣe ìdẹ̀ra fun yín. A sì ṣe yín ní ìjọ t’ó pọ̀ jùlọ

[7] Tí ẹ bá ṣe rere, ẹ ṣe rere fún ẹ̀mí ara yín. Tí ẹ bá sì ṣe aburú, fún ẹ̀mí ara yín ni. Nígbà tí àdéhùn ìkẹ́yìn bá dé, (A óò gbé ọmọ ogun mìíràn dìde) nítorí kí wọ́n lè kó ìbànújẹ́ ba yín àti nítorí kí wọ́n lè wọ inú Mọ́sálásí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wọ̀ ọ́ nígbà àkọ́kọ́ àti nítorí kí wọ́n lè pa ohun tí (àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl) jọba lórí rẹ̀ run pátápátá

[8] Ó lè jẹ́ pé Olúwa yín máa ṣàánú yín. Tí ẹ bá sì padà (síbi ẹ̀ṣẹ̀), A máa padà (síbi ẹ̀san). A sì ṣe iná Jahanamọ ní ẹ̀wọ̀n fún àwọn aláìgbàgbọ́

[9] Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí, ó ń fini mọ̀nà sí ọ̀nà tààrà, ó sì ń fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo t’ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san t’ó tóbi wà fún wọn

[10] Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n

[11] Ènìyàn ń tọrọ aburú bí ó ṣe ń tọrọ ohun rere; ènìyàn sì jẹ́ olùkánjú

[12] A ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran1 nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò. Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́

[13] Ènìyàn kọ̀ọ̀kan ni A ti la àyànmọ́ àti ìwé iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ lọ́rùn. A sì máa mú ìwé kan jáde fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó máa pàdé rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀

[14] Ka ìwé (iṣẹ́) rẹ. Ìwọ ti tó ní olùṣírò fún ẹ̀mí ara rẹ lónìí

[15] Ẹnikẹ́ni t’ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni t’ó bá sì ṣìnà, ó ń ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. A ò sì níí jẹ àwọn ẹ̀dá níyà títí A fi máa gbé òjíṣẹ́ kan dìde (sí wọn)

[16] Nígbà tí A bá sì gbèrò láti pa ìlú kan run, A máa pa àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà láṣẹ (rere). Àmọ́ wọ́n máa ṣèbàjẹ́ sínú ìlú. Ọ̀rọ̀ náà yó sì kò lé wọn lórí. A ó sì pa wọ́n rẹ́ pátápátá

[17] Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun lẹ́yìn (Ànábì) Nūh! Olúwa rẹ tó ní Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹrúsìn Rẹ̀

[18] Ẹni tí ó bá ń gbèrò (oore) ayé yìí (nìkan), A máa taari ohun tí A bá fẹ́ sí i nínú rẹ̀ ní kíákíá fún ẹni tí A bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, A máa ṣe iná Jahanamọ fún un; ó máa wọ inú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ, ẹni ẹ̀kọ̀

[19] Ẹni tí ó bá sì gbèrò (oore) ọ̀run, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ̀, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, iṣẹ́ wọn máa jẹ́ àtẹ́wọ́gbà (pẹ̀lú ẹ̀san rere)

[20] Àwọn wọ̀nyí (t’ó ń gbèrò oore ayé) àti àwọn wọ̀nyí (t’ó ń gbèrò oore ọ̀run), gbogbo wọn ni À ń ṣe oore ayé fún láti inú ọrẹ Olúwa rẹ. Wọn kò níí dí ọrẹ Olúwa rẹ lọ́wọ́ (fún ìkíní kejì nílé ayé)

[21] Wo bí A ṣe fún apá kan wọn lóore àjùlọ lórí apá kan (nílé ayé). Dájúdájú tọ̀run tún tóbi jùlọ ní ipò, ó sì tóbi jùlọ lóore àjùlọ

[22] Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu nítorí kí o má baà jókòó (sínú Iná) ní ẹni àbùkù, ẹni tí wọ́n máa dá ìṣòro rẹ̀ dá

[23] Olúwa rẹ pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí ìkíní kejì wọn bá dàgbà sí ọ lọ́dọ̀, má ṣe ṣíọ̀ sí wọn, má ṣe jágbe mọ́ wọn. Máa bá àwọn méjèèjì sọ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé

[24] Kí ó sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ láti fi bọ̀wọ̀ fún àwọn méjèèjì nípa ṣíṣe àánú wọn. Kí o sì sọ pé: "Olúwa Ẹlẹ́dàá mi, kẹ́ àwọn méjèèjì gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe rè mí ní kékeré

[25] Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, tí ẹ bá jẹ́ ẹni rere. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn fún àwọn olùronúpìwàdà

[26] Ẹ fún ẹbí ní ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Ẹ fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò tí agara dá (ní n̄ǹkan). Kí ẹ sì má ṣe ná dúkìá yín ní ìná-àpà

[27] Dájúdájú àwọn àpà, wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá Èṣù. Aláìmoore sì ni Èṣù jẹ́ sí Olúwa rẹ̀

[28] Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn (ìyẹn àwọn aláìní) láti wá ìkẹ́ kan tí ò ń retí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, bá wọn sọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀

[29] Má di ọwọ́ rẹ mọ́ ọrùn rẹ (má ya ahun), má sì tẹ́ ẹ sílẹ̀ tán pátápátá (má ya àpà), kí o má baà jókòó kalẹ̀ ní ẹni èébú (tí o bá jẹ́ ahun), ẹni tí kò níí sí lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́ (tí o bá jẹ́ àpà)

[30] Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀

[31] Ẹ má pa àwọn ọmọ yín nítorí ìpáyà òṣì. Àwa l’À ń pèsè fún àwọn àti ẹ̀yin. Dájúdájú pípa wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ t’ó tóbi

[32] Ẹ má ṣe súnmọ́ àgbèrè. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà burúkú. Ó sì burú ní ojú ọ̀nà

[33] Ẹ má pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ẹni tí wọ́n bá pa ní ìpa àbòsí, dájúdájú A ti fún alámòjúútó rẹ̀ ní agbára (láti gbẹ̀san). Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tayọ ẹnu- àlà níbi ìpànìyàn (nítorí pé) dájúdájú A máa ran (ẹbí òkú) lọ́wọ́ (láti gbẹ̀san)

[34] Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn, àyàfi ní ọ̀nà t’ó dára jùlọ, títí ó fi máa dàgbà. Kí ẹ sì mú àdéhùn ṣẹ. Dájúdájú àdéhùn jẹ́ ohun tí A ó bèèrè nípa rẹ̀

[35] Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún nígbà tí ẹ bá wọ̀n ọ́n. Ẹ fi ìwọ̀n t’ó tọ́ wọ̀n ọ́n. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ ní ìkángun

[36] Má ṣe tẹ̀lé ohun tí ìwọ kò nímọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn; ìkọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyẹn ni A óò bèèrè nípa rẹ̀

[37] Má ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga; dájúdájú ìwọ kò lè dá ilẹ̀ lu, ìwọ kò sì lè ga tó àpáta

[38] Gbogbo ìyẹn, aburú rẹ̀ jẹ́ ohun ìkórira lọ́dọ̀ Olúwa rẹ

[39] Ìyẹn wà nínú ohun tí Olúwa rẹ fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n (al-Ƙur’ān). Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu kí wọ́n má baà jù ọ́ sínú iná Jahanamọ ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀

[40] Ṣé Olúwa yín fi àwọn ọmọkùnrin ṣà yín lẹ́ṣà, Òun wá mú àwọn ọmọbìnrin nínú àwọn mọlāika (ní tiRẹ̀)? Dájúdájú ẹ mà ń sọ ọ̀rọ̀ ńlá (t’ó burú)

[41] Dájúdájú A ti ṣe àlàyé sínú al- Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìṣítí. Síbẹ̀síbẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún ìrántí)

[42] Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń wí, wọn ìbá wá ọ̀nà láti súnmọ́ (Allāhu) Onítẹ̀ẹ́-ọlá ni.”

[43] Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga ní gíga t’ó tóbi tayọ ohun tí wọ́n ń wí (ní àìda nípa Rẹ̀)

[44] Àwọn sánmọ̀ méjèèje, ilẹ̀ àti àwọn tí wọ́n wà nínú wọn ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Un. Kò sì sí kiní kan àfi kí ó ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Un. Ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbọ́ àgbọ́yé àfọ̀mọ́ wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn

[45] Nígbà tí o bá ń ké al-Ƙur’ān, A máa fi gàgá ààbò sáààrin ìwọ àti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́

[46] A fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Nígbà tí o bá sì dárúkọ Olúwa rẹ nìkan ṣoṣo nínú al-Ƙur’ān, wọ́n máa pẹ̀yìn wọn dà láti sá lọ

[47] Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń gbọ́ nígbà tí wọ́n bá ń tẹ́tí sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, nígbà tí àwọn alábòsí bá ń wí pé: “Ẹ kò tẹ̀lé ẹnì kan bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.”

[48] Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà

[49] Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a ti jẹrà, ṣé Wọ́n máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?”

[50] Sọ pé: "Ẹ di òkúta tàbí irin

[51] Tàbí (kí ẹ di) ẹ̀dá kan nínú ohun tí ó tóbi nínú ọkàn yín." Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò wí pé: “Ta ni Ó máa dá wa padà (fún àjíǹde)?” Sọ pé: “Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá yín ní ìgbà àkọ́kọ́ ni.” Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò mi orí wọn sí ọ (ní ti àbùkù) Nígbà náà, wọn yóò wí pé: “Ìgbà wo ni?” Sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé ó ti súnmọ́.”

[52] Ọjọ́ tí Allāhu yóò pè yín. Ẹ sì máa jẹ́pè pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Un. Ẹ sì máa rò pé ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀

[53] Sọ fún àwọn ẹrúsìn Mi pé kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ èyí t’ó dára jùlọ. Dájúdájú Èṣù yóò máa dá yánpọn-yánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Dájúdájú Èṣù jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn

[54] Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa yín. Tí Ó bá fẹ́, Ó máa kẹ yín. Tàbí tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa jẹ yín níyà. A kò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ lórí wọn

[55] Olúwa rẹ nímọ̀ jùlọ nípa àwọn t’ó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú A ti ṣe oore àjùlọ fún apá kan àwọn Ànábì lórí apá kan. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr

[56] Sọ pé: "Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀, (ẹ máa rí i pé) wọn kò ní ìkápá láti gbé ìnira kúrò tàbí láti ṣe ìyípadà kan fun yín

[57] Àwọn wọ̀nyẹn tí wọ́n ń pè (lẹ́yìn Rẹ̀) ń wá àtẹ̀gùn sọ́dọ̀ Olúwa wọn ni! - Èwo nínú wọn l’ó súnmọ́ (Allāhu) jùlọ (báyìí)? – Àwọn náà ń retí ìkẹ́ Allāhu, wọ́n sì ń páyà ìyà Rẹ̀. Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ jẹ́ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún

[58] Kò sí ìlú kan (t’ó ṣàbòsí) àfi kí Àwa pa á rẹ́ ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde tàbí kí Á jẹ ẹ́ níyà líle. Ìyẹn wà ní kíkọ sílẹ̀ nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ)

[59] Àti pé kò sí ohun tí ó dí Wa lọ́wọ́ láti fi àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) ránṣẹ́ bí kò ṣe pé àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti pè é nírọ́. A fún ìjọ Thamūd ní abo ràkúnmí; (àmì) t’ó fojú hàn kedere ni. Àmọ́ wọ́n ṣàbòsí sí i. A ò sì níí fi àwọn àmì ránṣẹ́ bí kò ṣe fún ìdẹ́rùbà

[60] (Rántí) nígbà tí A sọ fún ọ pé: “Dájúdájú Olúwa rẹ yí àwọn ènìyàn po (pẹ̀lú agbára Rẹ̀). Àti pé A kò ṣe ìran (wíwò) tí A fi hàn ọ́ àti igi (zaƙūm) tí A ṣẹ́bi lé nínú al-Ƙur’ān ní kiní kan bí kò ṣe pé (ó jẹ́) àdánwò fún àwọn ènìyàn. À ń dẹ́rù bà wọ́n, àmọ́ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìwà àgbéré t’ó tóbi

[61] (Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: "Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam." Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs. Ó wí pé: “Ṣé kí n̄g forí kanlẹ̀ kí ẹni tí O fi amọ̀ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni?”

[62] Ó wí pé: "Sọ fún mi nípa èyí tí O gbé àpọ́nlé fún lórí mí, (nítorí kí ni?) Dájúdájú tí O bá lè lọ́ mi lára di Ọjọ́ Àjíǹde, dájúdájú mo máa jẹgàba lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀

[63] (Allāhu) sọ pé: "Máa lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn, dájúdájú iná Jahanamọ ni ẹ̀san yín. (Ó sì jẹ́) ẹ̀san t’ó kún kẹ́kẹ́

[64] Fi ohùn rẹ kó ẹni tí agbára rẹ bá ká nínú wọn láyà jẹ. Fi àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin rẹ àti ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ rẹ pè wọ́n (sínú ìṣìnà). Kópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Kí o sì ṣe ìlérí fún wọn." Èṣù kò sì níí ṣe ìlérí fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn

[65] Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn. Olúwa rẹ sì tó ní Olùṣọ́

[66] Olúwa yín ni Ẹni t’Ó ń mú ọkọ̀ ojú-omi rìn fun yín nítorí kí ẹ lè wá nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláàánú fun yín

[67] Nígbà tí ìnira bá fọwọ́ bà yín lójú omi, ẹni tí ẹ̀ ń pè yó sì dòfo (mọ yín lọ́wọ́) àfi Òun nìkan (Allāhu). Nígbà ti Ó bá sì gbà yín là (tí ẹ) gúnlẹ̀, ẹ̀ ń gbúnrí (kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀). Ènìyàn sì jẹ́ aláìmoore

[68] Ṣé ẹ fọkàn balẹ̀ pé (Allāhu) kò lè mú apá kan ilẹ̀ ri mọ yín lẹ́sẹ̀ ni? Tàbí pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín? Lẹ́yìn náà, ẹ̀ o sì níí rí olùṣọ́ kan tí ó máa gbà yín là

[69] Tàbí ẹ fọkàn balẹ̀ pé (Allāhu) kò níí padà mu yín wá sí (orí omi) nígbà mìíràn ni; tí Ó máa rán ìjì atẹ́gùn si yín, tí Ó sì máa tẹ̀ yín rì (sínú omi) nítorí pé ẹ ṣàì moore? Lẹ́yìn náà, ẹ ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ kan t’ó máa ba yín gbẹ̀san lára Wa

[70] Dájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam; A gbé wọn rìn lórí ilẹ̀ àti lórí omi; A fún wọn ní ìjẹ-ìmu nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa; A sì ṣoore àjùlọ fún wọn gan-an lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí A dá

[71] Ní ọjọ́ tí A óò máa pe gbogbo ènìyàn pẹ̀lú aṣíwájú wọn . Nígbà náà, ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ìwé (iṣẹ́) rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò máa ka ìwé (iṣẹ́) wọn. A ò sì níí ṣàbòsí bín-íntín sí wọn

[72] Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ afọ́jú (nípa ’Islām) nílé ayé yìí, òun ni afọ́jú ní ọ̀run. Ó sì (ti) ṣìnà jùlọ

[73] Wọ́n fẹ́ẹ̀ kó ìyọnu bá ọ nípa n̄ǹkan tí A mú wá fún ọ ní ìmísí nítorí kí o lè hun n̄ǹkan mìíràn t’ó yàtọ̀ sí i nípa Wa. Nígbà náà, wọn ìbá mú ọ ní ọ̀rẹ́ àyò

[74] Tí kò bá jẹ́ pé A fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ ni, dájúdájú o fẹ́ẹ̀ fi n̄ǹkan díẹ̀ tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn

[75] Nígbà náà, Àwa ìbá jẹ́ kí o tọ́ ìlọ́po (ìyà) ìṣẹ̀mí ayé àti ìlọ́po (ìyà lẹ́yìn) ikú wò. Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí olùrànlọ́wọ́ kan tí ó máa gbà ọ́ sílẹ̀ níbi ìyà Wa

[76] Wọ́n fẹ́ẹ̀ kó ọ láyà jẹ nínú ìlú nítorí kí wọ́n lè lé ọ jáde kúrò nínú rẹ̀. Nígbà náà, àwọn náà kò níí wà nínú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ tayọ ìgbà díẹ̀

[77] (Èyí jẹ́) ìṣe (Allāhu) lórí àwọn tí A ti rán níṣẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ṣíwájú rẹ. O ò sì níí rí ìyípadà kan fún ìṣe Wa

[78] Gbé ìrun kíkí dúró ní (ìgbà tí) òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí alẹ́ yóò fi lẹ́. Àti pé ìrun Subh, dájúdájú ìrun Subh jẹ́ ohun tí (àwọn mọlāika alẹ́ àti ọ̀sán) yóò jẹ́rìí sí

[79] Àti pé nínú òru, fi kíké al-Ƙur’ān (lórí ìrun) ṣàì sùn. (Èyí jẹ́) iṣẹ́ àṣegbọrẹ fún ọ. Láìpẹ́, Olúwa rẹ yóò gbé ọ sí àyè ọpẹ́

[80] Sọ pé: “Olúwa mi, mú mi wọ inú ìlú ní ìwọ̀lú ọ̀nà òdodo. Mú mi jáde kúrò nínú ìlú ní ìjáde ọ̀nà òdodo. Kí O sì fún mi ní àrànṣe t’ó lágbára láti ọ̀dọ̀ Rẹ

[81] Sọ pé: “Òdodo dé. Irọ́ sì sá lọ. Dájúdájú irọ́ jẹ́ ohun tí ó máa sá lọ.”

[82] À ń sọ ohun tí ó jẹ́ ìwòsàn àti ìkẹ́ kalẹ̀ sínú al-Ƙur’ān fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (al-Ƙur’ān) kò sì ṣàlékún fún àwọn alábòsí bí kò ṣe òfò

[83] Nígbà tí A bá ṣèdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò níbi òdodo), ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù

[84] Sọ pé: "Ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣiṣẹ́ lórí àdámọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mọ̀nà

[85] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ẹ̀mí. Sọ pé: “Ẹ̀mí ń bẹ nínú àṣẹ Olúwa mi. A ò sì fun yín nínú ìmọ̀ bí kò ṣe díẹ̀.”

[86] Àti pé dájúdájú tí A bá fẹ́ ni, A ìbá kúkú gba ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ). Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí aláàbò kan tí ó máa là ọ́ lọ́dọ̀ Wa

[87] Àyàfi ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ (ni kò fi ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú oore àjùlọ Rẹ̀ lórí rẹ tóbi

[88] Sọ pé: “Dájúdájú tí àwọn ènìyàn àti àlùjànnú bá para pọ̀ láti mú irú al-Ƙur’ān yìí wá, wọn kò lè mú irú rẹ̀ wá, apá kan wọn ìbáà jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún apá kan

[89] Dájúdájú A ti fi àkàwé kọ̀ọ̀kan ṣàlàyé (oríṣiríṣi) fún àwọn ènìyàn sínú al-Ƙur’ān yìí. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá

[90] Wọ́n sì wí pé: “A kò níí gbà ọ́ gbọ́ títí o máa fi mú omi ìṣẹ́lẹ̀rú ṣẹ́ yọ fún wa

[91] Tàbí kí o ní ọgbà oko dàbínù àti ọgbà oko àjàrà, tí o sì máa jẹ́ kí àwọn odò ṣàn kọ já dáadáa láààrin wọn

[92] Tàbí kí o jẹ́ kí sánmọ̀ já lù wá ní kélekèle gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ (pé Allāhu lè ṣe bẹ́ẹ̀). Tàbí kí o mú Allāhu àti àwọn mọlāika wá (bá wa) ní ojúkojú

[93] Tàbí kí o ní ilé wúrà kan, tàbí kí o gun òkè sánmọ̀ lọ. A kò sì níí gba gígun-sánmọ̀ rẹ gbọ́ títí o fi máa sọ tírà kan tí a óò máa ké kalẹ̀ fún wa.” Sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa mi, ǹjẹ́ mo jẹ́ kiní kan bí kò ṣe Òjíṣẹ́ abara?”

[94] Kò sí ohun tí ó kọ̀ fún àwọn ènìyàn láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Ṣé Allāhu rán Òjíṣẹ́ abara níṣẹ́ ni?”

[95] Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́.”

[96] Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.”

[97] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Àti pé A máa kó wọn jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìdojúbolẹ̀. (Wọn yóò di) afọ́jú, ayaya àti odi. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Nígbàkígbà tí Iná bá jó lọọlẹ̀, A máa ṣàlékún jíjò (rẹ̀) fún wọn

[98] Ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé, wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a sì ti jẹrà, ṣé wọ́n tún máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?”

[99] Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ lágbára láti ṣẹ̀dá irú wọn (mìíràn)? Ó sì máa fún wọn ní gbèdéke àkókò kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn alábòsí kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá

[100] Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin l’ẹ ni ìkápá lórí àwọn ilé ọrọ̀ ìkẹ́ Olúwa mi ni, nígbà náà ẹ̀yin ìbá diwọ́ mọ́ ọn ní ti ìbẹ̀rù òṣì. Ènìyàn sì jẹ́ ahun

[101] Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní àwọn àmì mẹ́sàn-án t’ó yanjú. Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè wò. Rántí, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ wọn, Fir‘aon wí fún un pé: “Dájúdájú èmi lérò pé eléèdì ni ọ́, Mūsā.”

[102] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O kúkú mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó sọ àwọn (àmì) wọ̀nyí kalẹ̀ bí kò ṣe Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (ó sì jẹ́) àmì t’ó yanjú. Dájúdájú èmi náà lérò pé ẹni ìparun ni ọ́, Fir‘aon.”

[103] Nítorí náà, (Fir‘aon) fẹ́ kó wọn láyà jẹ lórí ilẹ̀. A sì tẹ òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ rì pátápátá

[104] A sì sọ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lẹ́yìn (ikú) rẹ̀ pé: “Ẹ máa gbé orí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí Àdéhùn Ìkẹ́yìn bá dé, A óò mú gbogbo yín wá ní àpapọ̀ (ní ọjọ́ ẹ̀san)

[105] A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. A kò sì rán ọ níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀

[106] Àti pé al-Ƙur’ān, A ṣàlàyé rẹ̀ (fún ọ) nítorí kí o lè ké e fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀. oríṣi ìsọ̀kalẹ̀ méjì l’ó wà fún al-Ƙur’ān. Ìsọ̀kalẹ̀ kìíní ni ìsọ̀kalẹ̀ olódidi láti inú Laohul-Mahfuṭḥ sínú sánmọ̀ ilé ayé. Ìsọ̀kalẹ̀ yìí l’ó ṣẹlẹ̀ nínú òru Laelatul-ƙọdr. Èyí l’ó jẹyọ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:185 sūrah ad-Dukān; 44:3 àti sūrah al-Ƙọdr’ 97:1. Ìsọ̀kalẹ̀ kejì ni ìsọ̀kalẹ̀ onídíẹ̀díẹ̀ láti inú sánmọ̀ ilé ayé sórí ilẹ̀ ayé. Èyí ṣẹlẹ̀ fún òǹkà ọdún mẹ́tàlélógún. Ìsọ̀kalẹ̀ yìí ni āyah yìí ń sọ nípa rẹ̀

[107] Sọ pé: “Ẹ gba al-Ƙur’ān gbọ́ tàbí ẹ ò gbà á gbọ́, dájúdájú àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀, tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu)

[108] Wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa wa. Dájúdájú àdéhùn Olúwa wa máa wá sí ìmúṣẹ ni.”

[109] Wọ́n ń dojú bolẹ̀, tí wọ́n ń sunkún (fún Allāhu. Al-Ƙur’ān) sì ń ṣàlékún ìtẹríba fún wọn

[110] Sọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).” Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn

[111] Kí o sì sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò yẹpẹrẹ áḿbọ̀sìbọ́sí pé Ó máa wá bùkátà sí olùrànlọ́wọ́.” Gbé títóbi fún Un gan-an

Àpátapò

Surah 18

[1] Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì dojú ọ̀rọ̀ kan rú nínú rẹ̀

[2] (al-Ƙur’ān) fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nítorí kí (Ànábì) lè fi ṣe ìkìlọ̀ ìyà líle láti ọ̀dọ̀ (Allāhu) àti nítorí kí (Ànábì) lè fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san rere ń bẹ fún wọn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra)

[3] Wọn yóò máa gbé nínú rẹ̀ lọ títí láéláé

[4] Àti nítorí kí (Ànábì) lè ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn t’ó wí pé: “Allāhu mú ẹnì kan ní ọmọ.”

[5] Kò sí ìmọ̀ fún àwọn àti bàbá wọn nípa rẹ̀. Ọ̀rọ̀ t’ó ń jáde lẹ́nu wọn tóbi. Dájúdájú wọn kò wí kiní kan bí kò ṣe irọ́

[6] Nítorí náà, nítorí kí ni o ṣe máa fi ìbànújẹ́ para rẹ lórí ìgbésẹ̀ wọn pé wọn kò gba ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí gbọ́

[7] Dájúdájú Àwa ṣe ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún ará-ayé nítorí kí Á lè dán wọn wò (pé) èwo nínú wọn l’ó máa dára jùlọ níbi iṣẹ́ ṣíṣe (fún ẹ̀sìn)

[8] Àti pé dájúdájú Àwa máa sọ n̄ǹkan tí ń bẹ lórí (ilẹ̀) di erùpẹ̀ gbígbẹ tí kò níí hu irúgbìn

[9] Tàbí o lérò pé dájúdájú àwọn ará inú ihò àpáta àti wàláhà orúkọ wọn jẹ́ èèmọ̀ kan nínú àwọn àmì Wa

[10] Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà kóra wọn sínú ihò àpáta, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, kí O ṣe ìmọ̀nà ní ìrọ̀rùn fún wa nínú ọ̀rọ̀ wa.”

[11] A kùn wọ́n l’óorun àsùnpiyè nínú ihò àpáta f’ọ́dún gbọọrọ

[12] Lẹ́yìn náà, A gbé wọn dìde nítorí kí Á lè ṣàfi hàn èwo nínú ìjọ méjèèjì l’ó mọ gbèdéke òǹkà ọdún t’ó lò (nínú ihò àpáta náà)

[13] Àwa ń sọ ìròyìn wọn fún ọ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n. Wọ́n gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. A sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn

[14] A sì kì wọ́n lọ́kàn nígbà tí wọ́n dìde, tí wọ́n sọ pé: "Olúwa wa ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. A ò sì níí pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀. (Tí a bá pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀) dájúdájú a ti pa irọ́ nìyẹn

[15] Àwọn ìjọ wa wọ̀nyí sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu. Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹ̀rí t’ó yanjú wá nípa wọn? Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu

[16] (Àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fúnra wọn pé:) nígbà tí ẹ bá yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, tí ẹ sì wá ibùgbé sínú ihò àpáta, Olúwa yín yóò tẹ́ nínú ìkẹ́ Rẹ̀ sílẹ̀ fun yín. Ó sì máa ṣe ọ̀rọ̀ yín ní ìrọ̀rùn fun yín

[17] O máa rí òòrùn nígbà tí ó bá yọ, ó máa yẹ̀bá kúrò níbi ihò wọn sí ọwọ́ ọ̀tún. Nígbà tí ó bá tún wọ̀, ó máa fi wọ́n sílẹ̀ sí ọwọ́ òsì. Wọ́n sì wà nínú àyè tí ó fẹjú nínú ihò àpáta. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ atọ́ni-sọ́nà kan fún un

[18] O máa lérò pé wọ́n lajú sílẹ̀ ni, ojú oorun ni wọ́n sì wà. A sì ń yí wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ padà sọ́tùn-ún sósì. Ajá wọn sì na apá rẹ̀ méjèèjì sílẹ̀ ní gbàgéde àpáta. Tí ó bá jẹ́ pé o yọjú wò wọ́n ni, ìwọ ìbá pẹ̀yìn dà láti họ fún wọn, ìwọ ìbá sì kún fún ìbẹ̀rù-bojo láti ara wọn

[19] Báyẹn (ni wọ́n wà) tí A fi gbé wọn dìde padà nítorí kí wọ́n lè bi ara wọn léèrè ìbéèrè. Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ìgbà wo lẹ ti wà níbí?” Wọ́n sọ pé: “A wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìdajì ọjọ́.” Wọ́n sọ pé: “Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ìgbà tí ẹ ti wà níbí.” Nítorí náà, ẹ gbé ọ̀kan nínú yín dìde lọ sí inú ìlú pẹ̀lú owó fàdákà yín yìí. Kí ó wo èwó nínú oúnjẹ ìlú l’ó mọ́ jùlọ, kí ó sì mú àsè wá fun yín nínú rẹ̀. Kí ó ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnì kan kan fura si yín

[20] (Nítorí pé) dájúdájú tí wọ́n bá fi lè mọ̀ nípa yín, wọn yóò jù yín lókò tàbí kí wọ́n da yín padà sínú ẹ̀sìn wọn. (Tí ó bá sì fi rí bẹ́ẹ̀) ẹ ò níí jèrè mọ́ láéláé nìyẹn

[21] Báyẹn ni A ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé dájúdájú Àkókò náà kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Rántí (nígbà tí àwọn ènìyàn) ń ṣe àríyànjiyàn láààrin ara wọn nípa ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sọ pé: "Ẹ mọ ilé kan lé wọn lórí. Olúwa wọn nímọ̀ jùlọ nípa wọn." Àwọn t’ó borí lórí ọ̀rọ̀ wọn sì wí pé: “Dájúdájú a máa sọ orí àpáta wọn di mọ́sálásí.”

[22] Wọ́n ń wí pé: “Mẹ́ta ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹrin wọn.” Wọ́n tún ń wí pé: "Márùn-ún ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹfà wọn." Ọ̀rọ̀ t’ó pamọ́ fún wọn (ni wọ́n ń sọ). Wọ́n tún ń wí pé: “Méje ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹjọ wọn.” Sọ pé: "Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa òǹkà wọn. Kò sí (ẹni tí) ó mọ (òǹkà) wọn àfi àwọn díẹ̀. Nítorí náà, má ṣe bá wọn ṣe àríyànjiyàn nípa (òǹkà) wọn àfi (kí o fi) àríyànjiyàn (náà tì síbi ẹ̀rí) t’ó yanjú (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ yìí). Má sì ṣe bi ẹnì kan nínú wọn léèrè nípa (òǹkà) wọn

[23] Má ṣe sọ nípa kiní kan pé: “Dájúdájú èmi yóò ṣe ìyẹn ní ọ̀la.”

[24] Àyàfi (kí o fi kún un pé) "tí Allāhu bá fẹ́." Ṣe ìrántí Olúwa rẹ nígbà tí o bá gbàgbé (láti sọ bẹ́ẹ̀ lásìkò náà). Kí o sì sọ (fún wọn) pé: “Ó rọrùn kí Olúwa mi tọ́ mi sọ́nà pẹ̀lú èyí tí ó súnmọ́ jù èyí lọ ní ìmọ̀nà (fún yín).”

[25] Wọ́n wà nínú ihò àpáta wọn fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún. Wọ́n tún lo àlékún ọdún mẹ́sàn-án

[26] Sọ pé: “Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n lò (nínú ihò àpáta). TiRẹ̀ ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kì ni kò rí tán, kì sí ni kò gbọ́ tán! Kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Kò sì fi ẹnì kan ṣe akẹgbẹ́ nínú ìdájọ́ Rẹ̀.”

[27] Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí ó lè yí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ padà. Ìwọ kò sì lè rí ibùsásí kan yàtọ̀ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[28] Ṣe sùúrù fún ẹ̀mí rẹ láti wà pẹ̀lú àwọn t’ó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń wá Ojú rere Rẹ̀. Má ṣe fojú pa wọ́n rẹ́ láti wá ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Má sì ṣe tẹ̀lé ẹni tí A mú ọkàn rẹ̀ gbàgbé ìrántí Wa. Ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àṣejù

[29] Sọ pé: “Òdodo (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó gbàgbọ́. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ kí ó ṣàì gbàgbọ́. Dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn alábòsí, tí ọgbà rẹ̀ yóò yí wọn po. Tí wọ́n bá ń tọrọ omi mímu, A óò fún wọn ní omi mímu kan t’ó dà bí òjé idẹ gbígbóná, tí (ìgbóná rẹ̀) yó sì máa ṣe àwọn ojú. Ó burú ní mímu. Ó sì burú ní ibùkójọ

[30] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ráre

[31] Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn yóò máa fi góòlù ọrùn ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀. Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán aláwọ̀ ewéko (èyí tí ó) fẹ́lẹ́ àti (èyí tí) ó nípọn. Wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú lórí ibùsùn ọlá nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ó dára ní ẹ̀san. Ó sì dára ní ibùkójọ

[32] Fi àwọn ọkùnrin méjì kan ṣe àpẹẹrẹ fún wọn; A fún ọ̀kan nínú wọn ní ọgbà èso àjàrà méjì. A sì fi àwọn igi dàbínù yí wọn ká. A tún fi àwọn igi eléso là wọ́n láààrin

[33] Ìkíní kejì àwọn oko méjèèjì ń so èso wọn. Àwọn èso rẹ̀ kì í pẹ̀ dín. A sì jẹ́ kí odò ṣàn kọjá láààrin oko méjèèjì

[34] Ó ní èso (sẹ́). Ó sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó ń bá a jiyàn (báyìí) pé: “Èmi ní dúkìá lọ́wọ́ jù ọ́ lọ. Mo tún lérò lẹ́yìn jùlọ.”

[35] Ó wọ inú oko rẹ̀ lọ, ó sì ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, ó wí pé: “Èmi kò lérò pé èyí máa parun láéláé

[36] Èmi kò sì lérò pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé tí wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú mo tún máa rí ibùdésí t’ó dára ju èyí lọ.”

[37] Ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un nígbà tí ó ń jà á níyàn (báyìí) pé: “Ṣé o máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà, láti inú àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ́ ní ọkùnrin t’ó pé ní ẹ̀dá

[38] Ṣùgbọ́n ní tèmi, Olúwa mi, Òun ni Allāhu. Èmi kò sì níí sọ ẹnì kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi

[39] Nígbà tí o wọ inú ọgbà oko rẹ, kí ni kò mú ọ sọ pé: "Ohun tí Allāhu bá fẹ́! Kò sí agbára kan bí kò ṣe pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí o bá sì rí mi pé mo kéré sí ọ ní dúkìá àti ọmọ

[40] ó súnmọ́ kí Olúwa mi fún èmi náà ní ọgbà oko tí ó máa dára ju ọgbà oko tìrẹ. (Ó sì súnmọ́) kí Ó sọ ìyà kan kalẹ̀ sínú ọgbà oko rẹ láti sánmọ̀; ó sì máa di ilẹ̀ aṣálẹ̀

[41] Tàbí kí omi rẹ̀ gbẹ. O ò sì níí lè wá omi kàn

[42] Wọ́n sì pa èso rẹ̀ run pátápátá. Ó sì di ẹni t’ó ń fí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lura wọn pẹ́ẹ́pẹ́ nípa ohun tí ó ti ná sórí rẹ̀. Ó ti parun tòrùlé-tòrùlé rẹ̀. Ó sì ń wí pé: “Yéè! Èmi ìbá tí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi.”

[43] Kò ní ìjọ kan tí ó máa ràn án lọ́wọ́ mọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́

[44] Níbẹ̀ yẹn, ti Allāhu, Ọba Òdodo ni ìjọba. Ó lóore jùlọ ní ẹ̀san, Ó sì lóore jùlọ ní ìkángun (rere)

[45] Ṣe àkàwé ilé ayé fún wọn; ó dà bí omi tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀. Lẹ́yìn náà, ó ròpọ̀ mọ́ irúgbìn ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (irúgbìn) di gbígbẹ, tí atẹ́gùn ń fọ́nká. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[46] Ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé ni dúkìá àti àwọn ọmọ. Àwọn iṣẹ́ rere t’ó máa wà títí láéláé lóore jùlọ ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, ó sì lóore jùlọ ní ìrètí

[47] (Rántí) ọjọ́ tí A máa mú àwọn àpáta rìn lọ. O sì máa rí ilẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. A máa kó wọn jọ. A ò sì níí fi ẹnì kan sílẹ̀ nínú wọn

[48] Wọn yó sì kó wọn wá síwájú Olúwa rẹ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹ ti wá bá Wa (báyìí) gẹ́gẹ́ bí A ṣe da yín nígbà àkọ́kọ́. Àmọ́ ẹ sọ láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé A ò níí mú ọjọ́ àdéhùn ṣẹ fun yín

[49] A máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá kalẹ̀ (fún wọn). Nígbà náà, o máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn yóò máa bẹ̀rù nípa ohun tí ń bẹ nínú ìwé iṣẹ́ wọn. Wọn yóò wí pé: “Ègbé wa! Irú ìwé wo ni èyí ná; kò fi ohun kékeré àti ńlá kan sílẹ̀ láì kọ ọ́ sílẹ̀?” Wọ́n sì bá ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ níbẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣàbòsí sí ẹnì kan

[50] (Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àlùjànnú. Ó sì ṣàfojúdi sí àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ máa mú òun àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ ní aláfẹ̀yìntì lẹ́yìn Mi ni, ọ̀tá yín sì ni wọ́n. Pàṣípààrọ̀ t’ó burú ni fún àwọn alábòsí

[51] N̄g ò pè wọ́n sí dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti dídá àwọn gan-an alára. N̄g ò sì mú àwọn aṣinilọ́nà ní olùrànlọ́wọ́

[52] (Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò sọ pé: “Ẹ pe àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n).” Wọ́n pè wọ́n. Wọn kò sì dá wọn lóhùn. A sì ti fi kòtò ìparun sáààrin wọn

[53] Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì rí Iná. Wọ́n sì mọ̀ pé àwọn yóò kó sínú rẹ̀. Wọn kò sì níí rí ibùsásí kan nínú rẹ̀

[54] Dájúdájú A ti ṣe àlàyé oníran-ànran sínú al-Ƙur’ān fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú gbogbo àkàwé. Ènìyàn sì jẹ́ alátakò púpọ̀ ju ohunkóhun lọ

[55] Kò sí ohun t’ó dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn, (kò sì sí ohun t’ó dí wọn lọ́wọ́ láti) tọrọ àforíjìn Olúwa wọn, bí kò ṣe pé (wọ́n fẹ́) kí ìṣe (Allāhu nípa ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ dé bá àwọn náà tàbí kí ìyà dé bá wọn ní ojúkojú

[56] Àti pé A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ (lásán) àfi kí wọ́n jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń fi irọ́ ṣàtakò nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo. Wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn di yẹ̀yẹ́

[57] Ta sì l’ó ṣàbòsí ju ẹni tí wọ́n fi àwọn āyah Olúwa rẹ̀ ṣèrántí fún, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀, tí ó sì gbàgbé ohun tí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì tì síwájú? Dájúdájú Àwa fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. A sì fi èdídí sínú etí wọn. Tí ìwọ bá pè wọ́n sínú ìmọ̀nà, nígbà náà wọn kò sì níí mọ̀nà láéláé

[58] Olúwa rẹ, Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́, tí ó bá jẹ́ pé Ó máa fi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ mú wọn ni, ìbá tètè mú ìyà wá fún wọn. Ṣùgbọ́n àkókò àdéhùn (àjíǹde) wà fún wọn. Wọn kò sì níí rí ibùsásí kan lẹ́yìn rẹ̀

[59] Ìwọ́nyí ni àwọn ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n ṣàbòsí. A sì fún wọn ní àdéhùn fún ìparun wọn

[60] (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "N̄g ò níí yé rìn títí mo máa fi dé ibi tí odò méjì ti pàdé tàbí (títí) mo máa fi lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún

[61] Nígbà tí àwọn méjèèjì sì dé ibi tí odò méjì ti pàdé, wọ́n gbàgbé ẹja wọn. (Ẹja náà) sì bọ́ sí ojú ọ̀nà rẹ̀ (tí ó ti di) poro ọ̀nà nínú odò

[62] Nígbà tí àwọn méjèèjì ré kọjá (ibi tí odò méjì ti pàdé), ó sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Fún wa ní oúnjẹ ọ̀sán wa. Dájúdájú a ti ko wàhálà nínú ìrìn-àjò wa yìí

[63] (Ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀) sọ pé: "Sọ (ohun t’ó ṣẹlẹ̀) fún mi, nígbà tí a wà níbi àpáta! Dájúdájú mo ti gbàgbé ẹja náà (síbẹ̀)? Kò sì sí ohun tí ó mú mi gbàgbé rẹ̀ bí kò ṣe Èṣù, tí kò jẹ́ kí n̄g rántí rẹ̀. (Ẹja náà) sì ti mú ọ̀nà rẹ̀ tọ̀ lọ nínú odò pẹ̀lú ìyanu

[64] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Ibi tí ẹja ti lọ) yẹn ni ohun tí à ń wá.” Àwọn méjèèjì sì padà sẹ́yìn láti tọ orípa ẹsẹ̀ wọn bí wọ́n ṣe tọ̀ ọ́ wá

[65] Àwọn méjèèjì sì rí ẹrúsìn kan nínú àwọn ẹrúsìn Wa, tí A fún ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. A sì fún un ní ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Wa

[66] (Ànábì) Mūsā sọ fún un pé: “Ṣé kí n̄g tẹ̀lé ọ nítorí kí o lè kọ́ mi nínú ohun tí Wọ́n fi mọ̀ ọ́ ní ìmọ̀nà.” àmọ́ bí mùsùlùmí kọ̀ọ̀kan bá ṣe súnmọ́ Allāhu tó nínú ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù rẹ̀ nípa lílo òfin ẹ̀sìn ’Islām

[67] (Kidr) sọ pé: “Dájúdájú o ò lè ṣe sùúrù pẹ̀lú mi

[68] Àti pé báwo ni o ṣe lè ṣe sùúrù lórí ohun tí o ò fi ìmọ̀ rọkiri ká rẹ̀?”

[69] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí Allāhu bá fẹ́, ó máa bá mi ní onísùúrù. Mi ò sì níí yapa àṣẹ rẹ.”

[70] (Kidr) sọ pé: “Tí o bá tẹ̀lé mi, má ṣe bi mí ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan kan títí mo fi máa kọ́kọ́ mú ìrántí wá fún ọ nípa rẹ̀.”

[71] Nítorí náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n fi wọ inú ọkọ̀ ojú-omi. (Kidr) sì dá ọkọ̀ náà lu. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O ṣe dá a lu, (ṣé) kí àwọn èrò rẹ̀ lè tẹ̀ rì ni? Dájúdájú o ti ṣe n̄ǹkan aburú kan!”

[72] (Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé dájúdájú o ò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.”

[73] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Má ṣe bá mi wí nípa ohun tí mo gbàgbé. Má sì ṣe kó ìnira bá mi nínú ọ̀rọ̀ (ìrìn-àjò) mi (pẹ̀lú rẹ).”

[74] Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n fi pàdé ọmọdékùnrin kan. (Kidr) sì pa á. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) mímọ́, láì gba ẹ̀mí? Dájúdájú o ti ṣe n̄ǹkan t’ó burú o.”

[75] (Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé dájúdájú o ò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.”

[76] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí mo bá tún bi ọ́ nípa kiní kan lẹ́yìn rẹ̀, má ṣe bá mi rìn mọ́. Dájúdájú o ti mú àwáwí dé òpin lọ́dọ̀ mi.”

[77] Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú kan. Wọ́n tọrọ oúnjẹ lọ́dọ̀ àwọn ará ìlú náà. Wọ́n sì kọ̀ láti ṣe wọ́n ní àlejò. Àwọn méjèèjì sì bá ògiri kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ wó. (Kidr) sì gbé e dìde. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé o bá fẹ́, o ò bá sì gba owó-ọ̀yà lórí rẹ̀.”

[78] (Kidr) sọ pé: “Èyí ni òpínyà láààrin èmi àti ìwọ. Mo sì máa fún ọ ní ìtúmọ̀ ohun tí o ò lè ṣe sùúrù lórí rẹ̀.”

[79] Ní ti ọkọ̀ ojú-omi, ó jẹ́ ti àwọn mẹ̀kúnnù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí omi. Mo sì fẹ́ láti fi àlébù kàn án (nítorí pé) ọba kan wà níwájú wọn t’ó ń gba gbogbo ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú ipá

[80] Ní ti ọmọdékùnrin náà, àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. A sì ń bẹ̀rù pé kí ó màa kó ìtayọ ẹnu-àlà àti àìgbàgbọ́ bá àwọn méjèèjì

[81] Nítorí náà, A fẹ́ kí Olúwa àwọn méjèèjì pààrọ̀ rẹ̀ fún wọn pẹ̀lú (èyí) t’ó lóore jù ú lọ ní ti mímọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀) àti (èyí) t’ó súnmọ́ jù ú lọ ní ti ìkẹ́

[82] Nípa ti ògiri, ó jẹ́ ti àwọn ọmọdékùnrin, ọmọ òrukàn méjì kan nínú ìlú náà. Àpótí-ọrọ̀ kan sì ń bẹ fún àwọn méjèèjì lábẹ́ ògiri náà. Bàbá àwọn méjèèjì sì jẹ́ ẹni rere. Nítorí náà, Olúwa rẹ fẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà (bá dúkìá náà), kí wọ́n sì hú dúkìá wọn jáde (kí ó lè jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Mi ò dá a ṣe láti ọ̀dọ̀ ara mi; (Allāhu l’Ó pa mí láṣẹ rẹ̀). Ìyẹn ni ìtúmọ̀ ohun tí o ò lè ṣe sùúrù fún

[83] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Thul-Ƙọrneen. Sọ pé: “Mo máa mú ọ̀rọ̀ ìrántí wá fun yín nípa rẹ̀.”

[84] Dájúdájú Àwa fún un ní ipò lórí ilẹ̀. A sì fún un ní ọ̀nà t’ó lè gbà ṣe gbogbo n̄ǹkan (tí ó bá fẹ́ ṣe)

[85] Nítorí náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀

[86] títí ó fi dé ibùwọ̀ òòrùn ayé. Ó rí i tí ń wọ̀ sínú ìṣẹ́lẹ̀rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ dúdú kan. Ó sì bá àwọn ènìyàn kan níbẹ̀. A sọ fún un pé: “Thul-Ƙọrneen, yálà kí o jẹ wọ́n níyà tàbí kí o mú ohun rere jáde lára wọn.”

[87] (Allāhu) sọ pé: “Ní ti ẹni tí ó bá ṣàbòsí, láìpẹ́ A máa jẹ ẹ́ níyà. Lẹ́yìn náà, wọn máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì máa jẹ ẹ́ níyà t’ó burú

[88] Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, tirẹ̀ ni ẹ̀san rere. A ó sì sọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn fún un nínú àṣẹ Wa.”

[89] Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀

[90] títí ó fi dé ibùyọ òòrùn ayé. Ó rí i tí ń yọ lórí àwọn ènìyàn kan, tí A kò fún ní gàgá (ààbò) kan níbi òòrùn

[91] Báyẹn ni (Thul-Ƙọrneen ṣe ń tẹ̀ síwájú). Dájúdájú A rọkiriká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀

[92] Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀

[93] títí ó fi dé ààrin àpáta méjì. Ó sì bá àwọn ènìyàn kan níwájú rẹ̀. Wọn kò sì fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan (nínú èdè mìíràn)

[94] Wọ́n sọ pé: “Thul-Ƙọrneen, dájúdájú (ìran) Ya’jūj àti Ma’jūj ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ṣé kí á fún ọ ní owó-òde nítorí kí o lè bá wa mọ odi kan sáààrin àwa àti àwọn?”

[95] Ó sọ pé: "Ohun tí Olúwa mi fún mi nínú ipò lóore jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi agbára ràn mí lọ́wọ́ ni nítorí kí n̄g lè mọ odi sáààrin ẹ̀yin àti àwọn

[96] Ẹ máa fún mi ni ègígé irin títí di ìgbà tí ó fi máa bá ẹ̀gbẹ́ àpáta méjèèjì dọ́gba." Ó sọ pé: "Ẹ máa fẹ́ atẹ́gùn ẹwìrì (sí i lára) títí di ìgbà tí ó máa (pọ́n wẹ̀ẹ̀ bí) iná." Ó sọ pé: "Ẹ mu idẹ wá fún mi kí n̄g yọ́ ọ lé e lórí

[97] Nítorí náà, wọn kò lè gùn ún, wọn kò sì lè dá a lu

[98] Ó sọ pé: “Èyí ni ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi. Nígbà tí àdéhùn Olúwa mi bá dé, (Allāhu) yó sì sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àdéhùn Olúwa mi sì jẹ́ òdodo.”

[99] A máa fi àwọn (ènìyàn àti àlùjànnú) sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí apá kan wọn yó sì máa dàpọ̀ mọ́ apá kan. Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A ó sì kó gbogbo wọn jọ papọ̀ pátápátá

[100] Ní ọjọ́ yẹn, A ó sì fi iná Jahanamọ han àwọn aláìgbàgbọ́ kedere

[101] (Àwọn ni) àwọn tí ojú wọn wà nínú èbìbò nípa ìrántí Mi. Wọn kò sì lè gbọ́rọ̀

[102] Ṣé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé àwọn yóò mú àwọn ẹrúsìn Mi ní olùrànlọ́wọ́ lẹ́yìn Mi ni? Dájúdájú Àwa pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ ní ibùdésí fún àwọn aláìgbàgbọ́

[103] Sọ pé: “Ṣé kí Á fun yín ní ìró àwọn ẹni òfò jùlọ nípa iṣẹ́ (ọwọ́ wọn)

[104] (Àwọn ni) àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ nínú ìṣẹ̀mí ayé, (àmọ́ tí) wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ń ṣe iṣẹ́ rere

[105] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn àti ìpàdé Rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ wọn sì bàjẹ́. Nítorí náà, A ò níí jẹ́ kí wọ́n jámọ́ n̄ǹkan kan lórí ìwọ̀n ní Ọjọ́ Àjíǹde

[106] Jahanamọ, ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́, wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi di oníyẹ̀yẹ́

[107] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn ọgbà Firdaos ti wà fún wọn ní ibùdésí

[108] Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí fẹ́ kúrò nínú rẹ̀

[109] Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ibúdò jẹ́ tàdáà fún àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi, ibúdò kúkú máa tán ṣíwájú kí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi tó tán, kódà kí Á tún mú (ibúdò) irú rẹ̀ wá ní àlékún.”

[110] Sọ pé: “Abara ni èmi bí irú yín. Wọ́n ń fí ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀.”

Mọryamù

Surah 19

[1] Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d. ìyá ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) Òun l’Ó ṣà á lẹ́ṣà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà ìbá tí sọ àwọn òdodo wọ̀nyẹn nípa Mọryam ìyá Jésù. Ṣebí wọ́n kúkú fi ẹnu àbùkù kan Mọryam ẹ̀dá ni àwọn mìíràn tí Allāhu fi sọrí àwọn sūrah ọ̀rọ̀ Rẹ̀. A kúkú rí sūrah Muhammad gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí sūrah Mọryam. Àmọ́ ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó máa sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di olúwa àti olùgbàlà? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun ọmọ? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam ṣíṣe tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe Mọryam ní ẹ̀ṣà ènìyàn àmọ́ tí Allāhu kò ṣe ìyá àti bàbá Ànábì wa bẹ́ẹ̀ tí Allāhu fi sọrí ẹbí Mọryam a kúkú rí sūrah Ƙuraeṣ

[2] (Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀, (Ànábì) Zakariyyā

[3] (Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀

[4] Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi

[5] Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan

[6] (tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi

[7] Zakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A ò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀)

[8] Ó sọ pé: "Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an

[9] (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni (ó máa rí).” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan.”

[10] (Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi

[11] Nígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́

[12] Yahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré

[13] (Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu)

[14] (Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa

[15] Àlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde)

[16] Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn

[17] Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé

[18] (Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).”

[19] (Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.”

[20] Ó sọ pé: "Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè

[21] (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn l’ó máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí.”

[22] Nítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan t’ó jìnnà

[23] Ìrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: “Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá.”

[24] Nígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ

[25] Mi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ

[26] Nítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: "Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, mi ò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní

[27] Ó sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: "Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan aburú ńlá wá

[28] Arábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè

[29] Ó sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: “Báwo ni a ó ṣe bá ẹni t’ó wà lórí ìtẹ́, t’ó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?”

[30] (Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: "Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ni Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì. ẹ̀dá tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun ẹ̀dá tí ó juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun àti ẹ̀dá tí ó ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun lábẹ́ ìlànà àti òfin Ọlọ́hun. Ẹ̀dá náà kò sì níí yọ́nú sí ìlànà àti òfin mìíràn t’ó yàtọ̀ sí ti Ọlọ́hun.” Ẹni tí ó bá ń ṣe ìwọ̀nyẹn fún ohun mìíràn tàbí ẹlòmíìràn but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Ìtúmọ̀: “Nítorí náà nígbà náà pẹ̀lú ẹ̀mí mi pẹ̀lú ọkàn àti ara wa ni a fi gbà láti wà lábẹ́ òfin Rẹ̀. Ìwọ̀nba àṣìṣe tí a bá sì fi ara ṣe gẹ́gẹ́ bí àdámọ́ ènìyàn ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni ọ̀nà àbáyọ lórí rẹ̀. Aláforíjìn

[31] Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé)

[32] (Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú

[33] Àlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde)

[34] Ìyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasara) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀

[35] Kò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀

[36] Àti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà

[37] Àwọn ìjọ (yẹhudi àti nasara) sì yapa ẹnu (sí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba lọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde)

[38] Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa! Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ náà ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[39] Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́

[40] Dájúdájú Àwa l’A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí

[41] Mú (ìtàn) ’Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì

[42] Rántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: "Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan

[43] Bàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́

[44] Bàbá mi, má ṣe bọ Èṣù. Dájúdájú Èṣù jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé

[45] Bàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ Èṣù (nínú Iná)

[46] (Bàbá rẹ̀) wí pé: “Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, ’Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi wọ́ọ́rọ́wọ́ ná.”

[47] (’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi

[48] Àti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi

[49] Nígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì

[50] Àti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì ní kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa

[51] Sọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì

[52] A pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀

[53] Láti inú ìkẹ́ Wa A sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ

[54] Sọ ìtàn (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì

[55] Ó máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀

[56] Sọ ìtàn (Ànábì) ’Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì

[57] A sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀)

[58] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún

[59] Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn yòdòyìndìn ẹ̀mí. Láìpẹ́ wọn máa pàdé ìparun (nínú Iná)

[60] Àyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn

[61] (Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn sí ìpamọ́ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ

[62] Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́

[63] Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa

[64] Àwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yìí. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbé

[65] Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀

[66] Ènìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, Wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?”

[67] Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan

[68] Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn èṣù jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀

[69] Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan èyíkéyìí nínú wọn tí ó le jùlọ ní ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé

[70] Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn t’ó lẹ́tọ̀ọ́ sí wíwọ inú Iná

[71] Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀. Ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ dandan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ. 74:30-31. Bákan náà, kalmọh “wārid” t’ó jẹyọ nínú āyah 71 jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe “warada”. Nínú al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ méjì péré l’ó wà fún “warada”. “Warada” túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, ó sì wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah Hūd 11:98 àti sūrah al-’Anbiyā’

[72] igun kìíní kejì máa wá lábẹ́ àkórìn àwọn mọlāika kan ni. Ìyẹn ni pé àwọn mọlāika kan l’ó máa kó gbogbo ẹ̀dá lọ sórí afárá Iná nítorí pé

[73] Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) l’ó lóore jùlọ ní ibùgbé, l’ó sì dára jùlọ ní ìjókòó?”

[74] Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jùlọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí

[75] Sọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun

[76] Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn t’ó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ

[77] Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: “Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!”

[78] Ṣé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé

[79] Rárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun t’ó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà

[80] A ó sì jogún ohun t’ó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan

[81] Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára

[82] Rárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn

[83] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Àwa ń rán àwọn èṣù sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń tì wọ́n ní ìtìkutì (síbi ẹ̀ṣẹ̀)

[84] Nítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà

[85] (Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn

[86] A sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì

[87] Wọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé

[88] Wọ́n wí pé: "Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ

[89] Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá

[90] Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dà wó lulẹ̀ gbì

[91] fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé

[92] Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ

[93] Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn

[94] Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà

[95] Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan

[96] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn

[97] Nítorí náà, A kúkú ṣe kíké al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn (fún ọ) pẹ̀lú èdè abínibí rẹ nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ oníyàn-jíjà

[98] Mélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí

Ṭā-hā

Surah 20

[1] Tọ̄ hā

[2] A kò sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ láti kó wàhálà bá ọ

[3] Bí kò ṣe pé ó jẹ́ ìrántí fún ẹni t’ó ń páyà (Allāhu)

[4] (Ó jẹ́) ìmísí t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí Ó dá ilẹ̀ àti àwọn sánmọ̀ gíga

[5] Àjọkẹ́-ayé gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá

[6] TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú

[7] Tí o bá sọ ọ̀rọ̀ jáde, dájúdájú (Allāhu) mọ ìkọ̀kọ̀ àti ohun tí ó (tún) pamọ́ jùlọ

[8] Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ

[9] Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā dé ọ̀dọ̀ rẹ

[10] (Rántí) nígbà tí ó rí iná kan, ó sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró síbí. Dájúdájú èmi rí iná kan. Ó ṣeé ṣe kí n̄g rí ògúnná mú wá fun yín nínú rẹ̀ tàbí kí n̄g rí ojú ọ̀nà kan nítòsí iná náà.”

[11] Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é "Mūsā

[12] Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā

[13] Àti pé Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Nítorí náà, fi etí sí ohun tí A máa fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí

[14] Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi

[15] Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Ó súnmọ́ kí N̄g ṣàfi hàn rẹ̀ (pẹ̀lú àwọn àmì. Àkókò náà wà fún) kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́

[16] Nítorí náà, ẹni tí kò gbà á gbọ́, tí ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó ṣẹ́rí rẹ kúrò níbẹ̀, kí o má baà parun

[17] Kí ni ìyẹn lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ, Mūsā

[18] Ó sọ pé: “Ọ̀pá mi ni. Mò ń fi rọ̀gbọ̀kú. Mo tún ń fi já ewé fún àwọn àgùtàn mi. Mo sì tún ń lò ó fún àwọn bùkátà mìíràn.”

[19] (Allāhu) sọ pé: “Jù ú sílẹ̀, Mūsā.”

[20] Nígbà náà, ó jù ú sílẹ̀. Ó sì di ejò t’ó ń sáré

[21] (Allāhu) sọ pé: "Mú un dání, má sì ṣe bẹ̀rù. A máa dá a padà sí ìrísí rẹ̀ àkọ́kọ́

[22] Fi ọwọ́ rẹ mọ́ (abẹ́) apá rẹ, ó máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe taburú. (Ó tún jẹ́) àmì mìíràn

[23] Kí Á lè fi èyí t’ó tóbi nínú àwọn àmì Wa hàn ọ́

[24] Lọ sí ọ̀dọ̀ Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà

[25] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, ṣí ọkàn mi payá fún mi

[26] Ṣọ̀rọ̀ mi dìrọ̀rùn fún mi

[27] Tú kókó orí ahọ́n mi

[28] kí wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé

[29] Àti pé fún mi ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú àwọn ará ilé mi

[30] Hārūn, arákùnrin mi ni

[31] Fi kún mi lọ́wọ́

[32] Fi ṣakẹgbẹ́ mi nínú iṣẹ́ mi

[33] kí á lè ṣàfọ̀mọ́ (orúkọ) Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀

[34] kí á tún lè ṣèrántí Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀

[35] Dájúdájú Ìwọ ń rí wa.”

[36] (Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú A ti fún ọ ní ìbéèrè rẹ, Mūsā

[37] Àti pé dájúdájú A ti ṣe oore fún ọ nígbà kan rí

[38] (Rántí) nígbà tí A ṣípayá ohun tí A ṣípayá fún ìyá rẹ

[39] pé: “Ju Mūsā sínú àpótí. Kí o sì gbé e jù sínú agbami odò. Odò yó sì gbé e jù sí etí odò. Ọ̀tá Mi àti ọ̀tá rẹ̀ sì máa gbé e.” Mo sì da ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Mi bò ọ́ nítorí kí wọ́n lè tọ́jú rẹ lójú Mi.”

[40] (Rántí) nígbà tí arábìnrin rẹ ń rìn lọ, ó sì sọ pé: “Ṣé kí n̄g júwe ẹni tí ó máa gbà á tọ́ (fun yín)?” A sì dá ọ padà sọ́dọ̀ ìyá rẹ nítorí kí ó lè ní ìtutù ojú, kò sì níí banújẹ́. Àti pé o pa ẹ̀mí ẹnì kan. A sì mú ọ kúrò nínú ìbànújẹ́. A tún mú àwọn àdánwò kan bá ọ. O tún lo àwọn ọdún kan lọ́dọ̀ àwọn ará Mọdyan. Lẹ́yìn náà, o dé (ní àkókò) tí ó ti wà nínú kádàrá, Mūsā

[41] Mo sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà fún (iṣẹ́) Mi

[42] Lọ, ìwọ àti arákùnrin rẹ, pẹ̀lú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Mi. Kí ẹ sì má ṣe kọ́lẹ nínú ìrántí Mi

[43] Ẹ lọ bá Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà

[44] Ẹ sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀ fún un. Ó ṣeé ṣe kí ó lo ìṣítí tàbí kí ó páyà (Mi)

[45] Àwọn méjèèjì sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa ń páyà pé ó má yára jẹ wá níyà tàbí pé ó má tayọ ẹnu-àlà.”

[46] (Allāhu) sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà. Dájúdájú Èmi wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì; Mò ń gbọ (yín), Mo sì ń ri (yín).”

[47] Nítorí náà, ẹ lọ bá a, kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa méjèèjì. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ. Má ṣe fìyà jẹ wọ́n. Dájúdájú a ti mú àmì kan wá bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kí àlàáfíà sì máa bá ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà

[48] Dájúdájú Wọ́n ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí wa pé dájúdájú ìyà ń bẹ fún ẹni tí ó bá pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i

[49] (Fir‘aon) wí pé: “Ta ni Olúwa ẹ̀yin méjèèjì, Mūsā?”

[50] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa wa ni Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ìṣẹ̀dá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó tọ́ ọ sí ọ̀nà.”

[51] (Fir‘aon) wí pé: “Kí l’ó mú àwọn ìran àkọ́kọ́ (tí wọn kò fi mọ̀nà)?”

[52] (Ànábì Mūsā) sọ pé: "Ìmọ̀ rẹ̀ wà nínú tírà kan lọ́dọ̀ Olúwa mi. Olúwa mi kò níí ṣàṣìṣe. Kò sì níí gbàgbé

[53] (Òun ni) Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ ní pẹrẹsẹ fun yín. Ó sì la àwọn ọ̀nà sínú rẹ̀ fun yín. Ó sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì fi mú oríṣiríṣi jáde nínú àwọn irúgbìn ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

[54] Ẹ jẹ, kí ẹ sì fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè

[55] Láti ara erùpẹ̀ ni A ti da yín. Inú rẹ̀ sì ni A óò da yín padà sí. Láti inú rẹ̀ sì ni A óò ti mu yín jáde padà nígbà mìíràn

[56] Dájúdájú A ti fi àwọn àmì Wa hàn án, gbogbo rẹ̀. Àmọ́ ó pè é nírọ́. Ó sì kọ̀ jálẹ̀

[57] Ó wí pé: "Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè mú wa jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa pẹ̀lú idán rẹ ni, Mūsā

[58] Dájúdájú a máa mú idán irú rẹ̀ wá bá ọ. Nítorí náà, mú àkókò ìpàdé láààrin àwa àti ìwọ, tí àwa àti ìwọ kò sì níí yapa rẹ̀, (kí ó sì mú) àyè kan t’ó tẹ́jú

[59] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Àkókò ìpàdé yín ni ọjọ́ Ọ̀ṣọ́ (ìyẹn, ọjọ́ ọdún). Kí wọ́n sì kó àwọn ènìyàn jọ ní ìyálẹ̀ta.”

[60] Fir‘aon pẹ̀yìn dà. Ó sì sa ète rẹ̀ jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, ó dé (síbẹ̀)

[61] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ègbé yín ò! Ẹ má ṣe dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu nítorí kí Ó má baà fi ìyà pa yín rẹ́. Àti pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu) ti ṣòfò.”

[62] Wọ́n fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ láààrin ara wọn. Wọ́n sì tẹ̀ sọ̀rọ̀

[63] Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwọn méjèèjì yìí, òpìdán ni wọ́n o. Wọ́n fẹ́ mu yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ yín pẹ̀lú idán wọn ni. Wọ́n sì (fẹ́) gba ojú ọ̀nà yín t’ó dára jùlọ mọ yín lọ́wọ́

[64] Nítorí náà, ẹ kó ète yín jọ papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, kí ẹ tò wá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹni tí ó bá borí ní òní ti jèrè

[65] (Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, ìwọ ni o máa kọ́kọ́ ju (ọ̀pá sílẹ̀ ni) tàbí àwa ni a óò kọ́kọ́ jù ú sílẹ̀.”

[66] (Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà náà ni àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn bá ń yíra padà lójú rẹ̀ nípasẹ̀ idán wọn, bí ẹni pé dájúdájú wọ́n ń sáré

[67] (Ànábì) Mūsā sì pa ẹ̀rù inú ọkàn rẹ̀ mọ́ra

[68] A sọ pé: "Má ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ, ìwọ lo máa lékè

[69] Ju ohun tí ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ sílẹ̀. Ó sì máa gbé ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀ mì káló. Dájúdájú ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀, ète òpìdán ni. Òpìdán kò sì níí jèrè ní ibikíbi tí ó bá dé

[70] Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀ (fún Allāhu). Wọ́n wí pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa Hārūn àti Mūsā

[71] (Fir‘aon) wí pé: "Ṣé ẹ ti gbà á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín? Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Nítorí náà, dájúdájú mo máa gé àwọn ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Dájúdájú mo tún máa kàn yín mọ́ àwọn igi dàbínù. Dájúdájú ẹ̀yin yóò mọ èwo nínú wa ni ìyà (rẹ̀) yóò le jùlọ, tí ó sì máa pẹ́ jùlọ

[72] (Àwọn òpìdán) sọ pé: "Àwa kò níí gbọ́lá fún ọ lórí ohun tí ó dé bá wa nínú àwọn ẹ̀rí t’ó dájú, (a ò sì níí gbọ́lá fún ọ lórí) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá wa. Nítorí náà, dá ohun tí ó bá fẹ́ dá lẹ́jọ́. Ilé ayé yìí nìkan ni o ti lè dájọ́

[73] Dájúdájú àwa gba Olúwa wa gbọ́ nítorí kí Ó lè ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa àti ohun tí o jẹ wá nípá ṣe nínú idán pípa. Allāhu lóore jùlọ, Ó sì máa wà títí láéláé

[74] Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá wá bá Olúwa rẹ̀ ní (ipò) ẹlẹ́ṣẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un. Kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí wà lààyè

[75] Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá bá A (gẹ́gẹ́ bí) onígbàgbọ́ òdodo, tí ó sì ti ṣe iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn ipò gíga ń bẹ fún

[76] (Ohun ni) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (iṣẹ́ rẹ̀)

[77] Àti pé dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā báyìí pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru. Fi (ọ̀pá rẹ) na omi fún wọn (kí ó di) ojú ọ̀nà gbígbẹ nínú omi òkun. Má ṣe bẹ̀rù àlébá, má sì ṣe páyà (ìtẹ̀rì sínú omi òkun).”

[78] Fir‘aon sì tẹ̀lé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ohun tí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru nínú agbami odò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru

[79] Fir‘aon ṣi àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà; òun (náà) kò sì mọ̀nà

[80] Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú A ti gbà yín là lọ́wọ́ ọ̀tá yín. A sì ba yín ṣe àdéhùn ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àpáta. A sì sọ ohun mímu mọnu àti ohun jíjẹ salwā kalẹ̀ fun yín

[81] Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pa lésè fun yín. Ẹ má sì kọjá ẹnu àlà nínú rẹ̀ nítorí kí ìbínú Mi má baà kò le yín lórí. Ẹnikẹ́ni tí ìbínú Mi bá sì kò lé lórí, dájúdájú ó ti jábọ́ (sínú ìparun)

[82] Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà tí ó tún tẹ̀lé ìmọ̀nà

[83] Kí ni ó mú ọ kánjú ya àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, Mūsā

[84] Ó sọ pé: “Àwọn nìwọ̀nyí tí wọ́n ń tọ orípa mi bọ̀ (lẹ́yìn mi). Èmi sì kánjú wá sọ́dọ̀ Rẹ nítorí kí O lè yọ́nú sí mi ni, Olúwa mi.”

[85] (Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú Àwa ti dán ìjọ rẹ wò lẹ́yìn rẹ. Àti pé Sāmiriy ṣì wọ́n lọ́nà

[86] (Ànábì) Mūsā sì padà sọ́dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé Olúwa yín kò ti ba yín ṣe àdéhùn dáadáa ni? Ṣé àdéhùn ti pẹ́ jù lójú yín ni tàbí ẹ fẹ́ kí ìbínú kò le yín lórí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ẹ fi yapa àdéhùn mi

[87] Wọ́n wí pé: “Àwa kò fínnúfíndọ̀ yapa àdéhùn fúnra wa, ṣùgbọ́n wọ́n di ẹrù ọ̀ṣọ́ àwọn ènìyàn (Misrọ) rù wá lọ́rùn. A sì jù ú sínú iná (pẹ̀lú àṣẹ Sāmiriyy). Báyẹn náà sì ni Sāmiriyy ṣe ju tirẹ̀.”

[88] Ó sì (fi mọ) ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi kan jáde fún wọn, t’ó ń dún (bíi màálù). Wọ́n sì wí pé: "Èyí ni ọlọ́hun yín àti ọlọ́hun Mūsā. Àmọ́ ó ti gbàgbé (rẹ̀)

[89] Ṣé wọn kò rí i pé kò lè dá èsì ọ̀rọ̀ kan padà fún wọn ni, kò sì ní agbára láti kó ìnira tàbí àǹfààní kan bá wọn

[90] Àti pé dájúdájú Hārūn ti sọ fún wọn ṣíwájú pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, wọ́n kàn fi ṣe àdánwò fun yín ni. Dájúdájú Olúwa yín ni Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé mi. Kí ẹ sì tẹ̀lé àṣẹ mi.”

[91] Wọ́n wí pé: “A ò níí yé dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ títí (Ànábì) Mūsā yóò fi padà sọ́dọ̀ wa.”

[92] (Ànábì) Mūsā sọ pé: "Hārūn, kí ni ó kọ̀ fún ọ nígbà tí o rí wọn tí wọ́n ṣìnà

[93] láti tọ̀ mí wá? Ṣé o yapa àṣẹ mi ni

[94] (Ànábì Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi, má ṣe fi irungbọ̀n mi tàbí orí mi fà mí (mọ́ra). Dájúdájú èmi páyà pé ó máa sọ pé: 'O dá òpínyà sílẹ̀ láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. O ò sì ṣọ́ ọ̀rọ̀ mi

[95] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tìrẹ ti jẹ́, Sāmiriyy?”

[96] (Sāmiriyy) wí pé: “Mo rí ohun tí wọn kò rí. Mo sì bu ẹ̀kúnwọ́ kan níbi (erùpẹ̀) ojú ẹsẹ̀ (ẹṣin) Òjíṣẹ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl). Mo sì dà á sílẹ̀ (láti fi mọ ère). Báyẹn ni ẹ̀mí mi ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún mi.”

[97] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Nítorí náà, máa lọ. Dájúdájú (ìjìyà) rẹ nílé ayé yìí ni kí o máa wí pé, “Má fi ara kàn mí”. Àti pé dájúdájú ọjọ́ ìyà kan ń bẹ fún ọ tí Wọn kò níí gbé fò ọ́. Kí o sì wo ọlọ́hun rẹ, èyí tí o takú tì lọ́rùn, dájúdájú a máa dáná sun ún. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa ku eérú rẹ̀ dànù pátápátá sínú agbami odò

[98] Ọlọ́hun yin ni Allāhu nìkan, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan

[99] Báyẹn ni A ṣe ń sọ ìtàn fún ọ nínú àwọn ìró tí ó ti ṣíwájú. Láti ọ̀dọ̀ Wa sì ni A kúkú ti fún ọ ní ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān)

[100] Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbẹ̀, dájúdájú ó máa ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde

[101] Olùṣegbére ni wọ́n nínú (ìyà) rẹ̀. (Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀) sì burú fún wọn láti rù ní Ọjọ́ Àjíǹde

[102] Ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A sí máa kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ ní ọjọ́ yẹn, ojú wọn yó sì dúdú batakun

[103] Wọn yó sì máa sọ̀rọ̀ ní jẹ́ẹ́jẹ́ láààrin ara wọn pé: "Ẹ̀yin kò gbé ilé ayé tayọ (ọjọ́) mẹ́wàá

[104] Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí nígbà tí ẹni-abiyì jùlọ nínú wọn wí pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé tayọ ọjọ́ kan.”

[105] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn àpáta. Sọ pé: “Olúwa mi yóò kù wọ́n dànù tán ráúráú

[106] Nígbà náà, Ó máa fi wọ́n sílẹ̀ ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ gban̄sasa

[107] O ò sì níí rí ọ̀gbun tàbí gelemọ kan nínú rẹ̀

[108] Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò tẹ̀lé olùpèpè náà, kò níí sí yíyà kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ohùn yó sì palọ́lọ́ fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, o ò níí gbọ́ ohùn kan bí kò ṣe gìrìgìrì ẹsẹ̀

[109] Ní ọjọ́ yẹn, ìṣìpẹ̀ kò níí ṣe àǹfààní àfi ẹni tí Àjọkẹ́-ayé bá yọ̀ǹda fún, tí Ó sì yọ́nú sí ọ̀rọ̀ fún un

[110] (Allāhu) mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn. Àwọn kò sì fi ìmọ̀ rọkiri ká Rẹ̀

[111] Àwọn ojú yó sì wólẹ̀ fún Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá di àbòsí mẹ́rù ti pòfo

[112] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kí ó má ṣe páyà àbòsí tàbí ìrẹ́jẹ kan (láti ọ̀dọ̀ Allāhu)

[113] Báyẹn ni A ṣe sọ (ìrántí) kalẹ̀ ní ohun kíké pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. A sì ṣe àlàyé oníran-ànran ìlérí sínú rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún ìyà) tàbí nítorí kí ó lè jẹ́ ìrántí fún wọn

[114] Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga jùlọ. Má ṣe kánjú pẹ̀lú al-Ƙur’ān ṣíwájú kí wọ́n tó parí ìmísí rẹ̀ fún ọ. Kí o sì sọ pé: “Olúwa mi, ṣàlékún ìmọ̀ fún mi.”

[115] Dájúdájú A ṣe àdéhùn fún (Ànábì) Ādam ṣíwájú. Ṣùgbọ́n ó gbàgbé. A kò sì bá a pẹ̀lú ìpinnu ọkàn

[116] Nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam. Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó kọ̀.”

[117] Nítorí náà, A sọ pé: "Ādam, dájúdájú èyí ni ọ̀tá fún ìwọ àti ìyàwó rẹ. Nítorí náà, kò gbọdọ̀ mú ẹ̀yin méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí kí o má baà dààmú (fún ìjẹ-ìmu)

[118] Dájúdájú ebi kò níí pa ọ́, o ò sì níí rìn hòhò nínú rẹ̀

[119] Àti pé dájúdájú òǹgbẹ kò níí gbẹ ọ́ nínú rẹ̀, òòrùn kò sì níí pa ọ́

[120] Ṣùgbọ́n Èṣù kó ròyíròyí bá a; ó wí pé: “Ādam, ǹjẹ́ mo lè júwe rẹ sí igi gbére àti ìjọba tí kò níí tán?”

[121] Nítorí náà, àwọn méjèèjì jẹ nínú (èso) rẹ̀. Ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn; àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí da ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bo ara wọn. Ādam yapa àṣẹ Olúwa rẹ̀. Ó sì ṣìnà

[122] Lẹ́yìn náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà; Ó gba ìronúpìwàdà rẹ̀, Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà

[123] (Allāhu) sọ pé: "Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ pátápátá. Apá kan yín sì jẹ́ ọ̀tá sí apá kan - ẹ̀yin àti Èṣù. Nígbà tí ìmọ̀nà bá sì dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, kò níí ṣìnà, kò sì níí dààmú

[124] Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣẹ́rí kúrò níbi ìrántí Mi, dájúdájú ìṣẹ̀mí ìnira máa wà fún un nílé ayé. A sì máa gbé e dìde ní afọ́jú ní Ọjọ́ Àjíǹde.”

[125] (Ó) máa wí pé: “Olúwa mi, nítorí kí ni O fi gbé mi dìde ní afọ́jú? Mo ti jẹ́ olùríran tẹ́lẹ̀!”

[126] (Allāhu) sọ pé: "Báyẹn ni àwọn āyah Wa ṣe dé bá ọ, o sì gbàgbé rẹ̀ (o pa á tì). Ní òní, báyẹn ni wọ́n ṣe máa gbàgbé ìwọ náà (sínú Iná)

[127] Àti pé báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣejù, tí kò sì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa rẹ̀. Dájúdájú ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn le jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé

[128] Ṣé kò hàn sí wọn pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun ṣíwájú wọn, tí (àwọn wọ̀nyí náà) sì ń rìn kọjá ní ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn olóye

[129] Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan t’ó ṣíwájú àti gbèdéke àkókò kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn) ìbá ti di dandan

[130] Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí, kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ọpẹ́ fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti ṣíwájú wíwọ̀ rẹ̀. Ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní àwọn àsìkò alẹ́ àti ní àwọn abala ọ̀sán, kí ó retí (ẹ̀san) tí ó máa yọ́nú sí

[131] Má ṣe fẹjú rẹ sí ohun tí A fi ṣe ìgbádùn t’ó jẹ́ òdódó ìṣẹ̀mí ilé ayé fún àwọn ìran-ìran kan nínú wọn. (A fún wọn) nítorí kí Á lè fi ṣe àdánwò fún wọn ni. Arísìkí Olúwa rẹ lóore jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé

[132] Pa ará ilé rẹ láṣẹ ìrun kíkí, kí o sì ṣe sùúrù lórí rẹ̀. A ò níí bèèrè èsè kan lọ́wọ́ rẹ; Àwa l’À ń pèsè fún ọ. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún ìbẹ̀rù (Allāhu)

[133] Wọ́n wí pé: “Nítorí kí ni kò fi mú àmì kan wá fún wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Ṣé ẹ̀rí t’ó yanjú t’ó wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́ kò dé bá wọn ni

[134] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú A ti fi ìyà kan pa wọ́n run ṣíwájú rẹ̀ ni, wọn ìbá wí pé: "Olúwa wa nítorí kí ni O ò ṣe rán Òjíṣẹ́ kan sí wa, àwa ìbá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ ṣíwájú kí á tó yẹpẹrẹ, (kí á sì tó) kàbùkù

[135] Sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùretí (ìkángun).” Nítorí náà, ẹ máa retí (rẹ̀). Ẹ máa mọ ta ni èrò ọ̀nà tààrà àti ẹni t’ó mọ̀nà

Àwọn Wòlíì

Surah 21

[1] Ìṣírò-iṣẹ́ súnmọ́ fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì wà nínú ìfọ́núfọ́ra, tí wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo)

[2] Kò sí ìrántí titun kan tí ó máa dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àfi kí wọ́n gbọ́ ọ pẹ̀lú eré ṣíṣe

[3] Wọ́n fọ́núfọ́ra ni. Àwọn t’ó ṣàbòsí sì fi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (ààrin ara wọn) pamọ́ pé: "Ṣé èyí tayọ abara bí irú yín ni? Ṣé ẹ máa tẹ̀lé idán ni, nígbà tí ẹ̀yin náà ríran

[4] Ó sọ pé: “Olúwa mi mọ ọ̀rọ̀ t’ó ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.”

[5] Rárá, wọ́n tún wí pé: “Àwọn àlá tí ìtúmọ̀ rẹ̀ lọ́pọ̀ mọ́ra wọn ni (al-Ƙur’ān.” Wọ́n tún wí pé): “Rárá, ó hun ún ni.” (Wọ́n tún wí pé): “Rárá, eléwì ni. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó mú àmì kan wá fún wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi rán àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

[6] Kò sí àwọn t’ó gbàgbọ́ ṣíwájú wọn nínú àwọn ìlú tí A ti parẹ́ (lẹ́yìn ìsọ̀kalẹ̀ àmì). Ṣé àwọn sì máa gbàgbọ́ (nígbà tí àmì bá dé)

[7] A ò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀

[8] A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kò níí jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé). abara ni kì í ṣe ọlọ́hun. Allāhu àwọn òkú kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè ní ìbámu sí sūrah an-Naml; 27:80 sūrah ar-Rūm; 30:52 àti sūrah Fātir; 35:22. Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì padà di òkú tí wọ́n bò mọ́ inú sàréè nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:30. Kò sì sí āyah tààrà kan nínú al-Ƙur’ān tí ó yọ Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sílẹ̀ nínú àwọn òkú tí kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè. Àmọ́ hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé “Kò sí ẹnì kan tí ó máa sálámọ̀ sí mi àfi kí Allāhu dá ẹ̀mí mi padà sí mi lára títí mo máa fi dá sálámọ̀ náà padà fún un.” Abū Dāūd l’ó gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb ziyāratul-ƙubūr. Ṣeek al-Bāniy sọ pé “hadīth náà dára”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy. Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé “Dájúdájú ọjọ́ Jum‘ah wà nínú àwọn ọjọ́ yín t’ó lóore jùlọ; Wọ́n ṣẹ̀dá Ànábì Ādam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nínú rẹ̀ ní ìṣẹ̀lẹ̀ t’ó tayọ òye wa àmọ́ tí ó tẹnu Ànábì wa Muhammad olódodo (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jáde tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín.” Ẹnì kan nínú àwọn t’ó gba hadīth yìí wá sọ pé “Kí ni ìtúmọ̀ “tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín”? Tàbí kí ni ìtúmọ̀ “tí ohun tí ó máa fi darí yín sì máa wá láti ọ̀dọ̀ yín?” Ibnu Abī Thanb sì fèsì pé

[9] Lẹ́yìn náà, A mú àdéhùn Wa ṣẹ fún wọn. A sì gba àwọn Òjíṣẹ́ àti àwọn tí A bá fẹ́ là. A sì pa àwọn olùtayọ ẹnu-àlà run

[10] Dájúdájú A ti sọ tírà kan kalẹ̀ fun yín, tí ìrántí nípa ọ̀rọ̀ ara yín wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni

[11] Mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́, tí ó jẹ́ alábòsí! A sì gbé àwọn ìjọ mìíràn dìde lẹ́yìn wọn

[12] Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa (t’ó ń bọ̀), wọ́n sì ń sá lọ fún un

[13] Ẹ má ṣe sá lọ. Ẹ padà síbi n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fun yín àti àwọn ibùgbé yín nítorí kí A lè bi yín ní ìbéèrè

[14] Wọ́n wí pé: “Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”

[15] Igbe wọn yìí kò dúró títí A fi sọ wọ́n di koríko tí wọ́n gé, wọ́n sì dòkú kalẹ̀

[16] Àwa kò dá sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe

[17] Tí ó bá jẹ́ pé A gbèrò láti ṣèré ni, ọ̀dọ̀ Wa ni A kúkú tí máa ṣe é tí A bá jẹ́ olùṣe-(eré)

[18] Rárá o! À ń sọ òdodo lu irọ́ (mọ́lẹ̀ ni). Òdodo sì máa fọ́ agbárí irọ́. Irọ́ sì máa pòórá. Ègbé sì ni fun yín nípa ohun tí ẹ ń fi ròyìn (Rẹ̀ ní ti irọ́)

[19] TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé àwọn t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Rẹ̀, wọn kì í ṣègbéraga níbi ìjọ́sìn Rẹ̀. Àti pé wọ́n kò kọ́lẹ

[20] Wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ ní òru àti ní ọ̀sán; kò sì rẹ̀ wọ́n

[21] Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tí wọ́n mú jáde láti ara ilẹ̀, tí wọ́n ń jí òkú dìde ni

[22] Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ lẹ́yìn Allāhu, sánmọ̀ àti ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)

[23] Wọn kò níí bi (Allāhu) ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan tí Ó ń ṣe. Àwọn ni wọ́n máa bi ní ìbéèrè (nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn)

[24] Tàbí wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wa.” (Al-Ƙur’ān) yìí ni ìrántí nípa àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi àti ìrántí nípa àwọn t’ó ṣíwájú mi. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ òdodo; wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀

[25] A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.”

[26] Wọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un – Kò rí bẹ́ẹ̀; ẹrúsìn alápọ̀n-ọ́nlé ni wọ́n

[27] Wọn kì í ṣíwájú Allāhu sọ̀rọ̀. Wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀

[28] (Allāhu) mọ ohun t’ó ń bẹ níwájú wọn àti ohun t’ó ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì níí ṣìpẹ̀ (ẹnì kan) àfi ẹni tí (Allāhu) bá yọ́nú sí. Wọ́n tún ń páyà fún ìbẹ̀rù Rẹ̀

[29] Àti pé ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá wí pé: “Dájúdájú èmi ni ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀.” Nítorí ìyẹn sì ni A óò fi san án ní ẹ̀san iná Jahanamọ. Báyẹn sì ni A ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san

[30] Ṣé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kò rí i pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ lẹ̀ pọ̀ àti ilẹ̀ náà lẹ̀ pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, A sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, A sì ṣe gbogbo n̄ǹkan ní abẹ̀mí láti inú omi? Nítorí náà, ṣé wọn kò níí gbàgbọ́ ni? lílẹ̀-papọ̀” ìtúmọ̀ “fatƙ” sì ni “ẹ̀là

[31] A sì fi àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. A sì fi àwọn ọ̀nà fífẹ̀ sáààrin àwọn àpáta nítorí kí wọ́n lè rí ọ̀nà tọ̀

[32] A tún ṣe sánmọ̀ ní àjà tí wọ́n ń ṣọ́ (níbi jíjábọ́). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi àwọn àmì rẹ̀

[33] Òun ni Ẹni tí Ó dá òru àti ọ̀sán pẹ̀lú òòrùn àti òṣùpá. Ìkọ̀ọ̀kan (òòrùn àti òṣùpá) wà ní òpópónà roboto t’ó ń tọ̀

[34] A kò ṣe bíbẹ gbére fún abara kan ṣíwájú rẹ. Ǹjẹ́ tí o bá kú, àwọn sì ni olùṣegbére bí

[35] Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan l’ó máa tọ́ ikú wò. A sì máa fi aburú àti rere ṣàdánwò fun yín. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí

[36] Nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ bá rí ọ, wọn kò sì níí kà ọ́ kún kiní kan bí kò ṣe oníyẹ̀yẹ́ pé: “Ṣé èyí ni ẹni t’ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́hun yín?” Aláìgbàgbọ́ sì ni àwọn náà nípa ìrántí Àjọkẹ́-ayé

[37] Wọ́n fi ìkánjú ṣe ènìyàn. Mo máa fi àwọn àmì Mi hàn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe kán Mi lójú

[38] Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni ìlérí yìí yóò ṣẹ ná, tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

[39] Tí ó bá jẹ́ pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ mọ ìgbà tí wọn kò níí dá Iná dúró níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn, tí A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́, (wọn ìbá tí wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú)

[40] Ṣùgbọ́n (ìyà Iná) yóò bá wọn ní òjijì, nígbà náà ó máa kó ìdààmú bá wọn; wọn kò sì níí lè dá a padà. A ò sì níí sún (ìyà náà) síwájú fún wọn

[41] Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí àwọn t’ó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po

[42] Sọ pé: "Ta ni ẹni tí ó ń ṣọ yín ní òru àti ní ọ̀sán níbi ìyà Àjọkẹ́-ayé?" Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọkẹ́-ayé

[43] Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan t’ó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lẹ́yìn Wa ni? Wọn kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Wọn kò sì lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́dọ̀ Wa

[44] Bẹ́ẹ̀ ni, A fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn títí ìṣẹ̀mí ayé wọn fi gùn. Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń mú ilẹ̀ dínkù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn etí ìlú (wọnú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn). Nítorí náà, ṣé àwọn ni olùborí ni

[45] Sọ pé: “Ìmísí ni mo fi ń kìlọ̀ fun yín. Àwọn adití kò sì níí gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá ń kìlọ̀ fún wọn.”

[46] Àti pé dájúdájú tí abala kan nínú ìyà Olúwa rẹ bá fọwọ́ bà wọ́n, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò; dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.”

[47] A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò

[48] Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) Hārūn ní ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun t’ó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́), ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[49] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀. Olùpáyà sì ni wọ́n nípa Àkókò náà

[50] Èyí sì ni ìrántí oníbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Ṣé ẹ̀yin yóò takò ó ni

[51] Dájúdájú A ti fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní ìmọ̀nà tirẹ̀ ṣíwájú (kí ó tó dàgbà). Àwa sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀

[52] (Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ère wọ̀nyí tí ẹ̀ ń dúró tì lọ́rùn ṣe jẹ́ ná?”

[53] Wọ́n wí pé: “A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń jọ́sìn fún wọn ni.”

[54] Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

[55] Wọ́n wí pé: “Ṣé o mú òdodo wá fún wa ni tàbí ìwọ wà lára àwọn ẹlẹ́fẹ̀.”

[56] Ó sọ pé: "Rárá. Olúwa yin ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; Ẹni tí Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èmi sì wà nínú àwọn ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn

[57] Àti pé mo fi Allāhu búra, dájúdájú mo máa dète sí àwọn òrìṣà yín lẹ́yìn tí ẹ bá pẹ̀yìn dà, tí ẹ lọ

[58] Ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ àfi àgbà (òrìṣà) wọn nítorí kí wọ́n lè padà dé bá a

[59] Wọ́n wí pé: “Ta ni ó ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa? Dájúdájú onítọ̀un wà nínú àwọn alábòsí.”

[60] Wọ́n wí pé: “A gbọ́ tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n. Wọ́n ń pe (ọmọ náà) ní ’Ibrọ̄hīm.”

[61] Wọ́n wí pé: “Ẹ mú un wá han àwọn ènìyàn kí wọ́n lè jẹ́rìí lé e lórí.”

[62] Wọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ l’o ṣe èyí pẹ̀lú àwọn ọlọ́hun wa, ’Ibrọ̄hīm?”

[63] Ó sọ pé: “Rárá o, àgbà wọn yìí l’ó ṣe (wọ́n bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, ẹ bi wọ́n léèrè wò tí wọ́n bá máa ń sọ̀rọ̀.”

[64] Nígbà náà, wọ́n yíjú síra wọn, wọ́n sì wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni alábòsí.”

[65] Lẹ́yìn náà, wọ́n sorí kọ́ (wọ́n sì wí pé): “Ìwọ náà kúkú mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí kì í sọ̀rọ̀.”

[66] Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira ba yín lẹ́yìn Allāhu

[67] Ṣíọ̀ ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, ṣé ẹ̀yin kò níí ṣe làákàyè ni

[68] Wọ́n wí pé: “Ẹ dáná sun ún; kí ẹ sì ran àwọn ọlọ́hun yín lọ́wọ́, tí ẹ̀yin bá níkan-án ṣe.”

[69] A sọ pé: “Iná, di tútù àti àlàáfíà lára ’Ibrọ̄hīm.”

[70] Wọ́n gbèrò ète sí i, ṣùgbọ́n A ṣe wọ́n ní olófò jùlọ

[71] A sì gba òun àti Lūt là sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí fún gbogbo ẹ̀dá

[72] A ta á ní ọrẹ ọmọ, ’Is-hāƙ àti Ya‘ƙūb tí ó jẹ́ àlékún (ìyẹn, ọmọọmọ). Olúkùlùkù (wọn) ni A ṣe ní ẹni rere

[73] A ṣe wọ́n ní aṣíwájú t’ó ń tọ́ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Wọ́n sì jẹ́ olùjọ́sìn fún Wa

[74] (Ẹ rántí Ànábì) Lūt. A fún un ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì gbà á là nínú ìlú tí wọ́n ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ burúkú. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú, òbìlẹ̀jẹ́

[75] A sì mú un wọ inú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹni rere

[76] (Ẹ rántí Ànábì) Nūh, nígbà tí ó pe ìpè ṣíwájú (yín). A sì dá a lóhùn. A sì gba òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ìbànújẹ́ ńlá

[77] A sì ṣàrànṣe fún un lórí àwọn ènìyàn t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú. A sì tẹ̀ wọ́n rì pátápátá

[78] (Ẹ rántí Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n, nígbà tí àwọn méjèèjì ń ṣe ìdájọ́ lórí (ọ̀rọ̀) oko, nígbà tí àgùtàn ìjọ kan jẹko wọ inú oko náà. Àwa sì jẹ́ Olùjẹ́rìí sí ìdájọ́ wọn

[79] A sì fún (Ànábì) Sulaemọ̄n ní àgbọ́yé rẹ̀. Àti pé ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ni A fún ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì tẹ àwọn àpáta àti ẹyẹ ba; wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) pẹ̀lú (Ànábì) Dāwūd. Àwa l’A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀

[80] A tún fún un ní ìmọ̀ nípa ṣíṣe ẹ̀wù irin fun yín nítorí kí ó lè jẹ́ odi ìṣọ́ fun yín níbi ogun yín. Nítorí náà, ǹjẹ́ olùdúpẹ́ (fún Allāhu) ni ẹ̀yin bí

[81] A sì tẹ atẹ́gùn líle lórí ba fún (Ànábì) Sulaemọ̄n. Ó ń gbé e lọ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí. A sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[82] Nínú àwọn èṣù, àwọn t’ó ń wa kùsà òkun tún wà fún un. Wọ́n tún ń ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn. Àwa sì ń jẹ́ Olùṣọ́ fún wọn

[83] (Ẹ rántí Ànábì) ’Ayyūb, nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Dájúdájú ọwọ́ ìnira ti kàn mí. Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú

[84] A sì jẹ́ ìpè rẹ̀. A mú gbogbo ìnira rẹ̀ kúrò fún un. A tún fún un ní àwọn ẹbí rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn; (ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn olùjọ́sìn (fún Wa)

[85] (Ẹ rántí Ànábì) ’Ismọ̄‘īl àti (Ànábì) ’Idrīs àti (Ànábì) Thul-Kifl; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) wà nínú àwọn onísùúrù

[86] A sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni rere

[87] (Ẹ rántí) ẹlẹ́ja, nígbà tí ó bá ìbínú lọ, ó sì lérò pé A ò níí gbá òun mú. Ó sì pe (Olúwa rẹ̀) nínú àwọn òkùnkùn (inú ẹja) pé: "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn alábòsí

[88] A jẹ́ ìpè rẹ̀. A sì gbà á là nínú ìbànújẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là

[89] (Ẹ rántí Ànábì) Zakariyyā nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Olúwa mi, má fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan (tí kò níí bímọ). Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùjogún.”

[90] A jẹ́ ìpè rẹ̀. A sì ta á lọ́rẹ ọmọ, (Ànábì) Yahyā. A sì ṣe àtúnṣe ìyàwó rẹ̀ fún un. Dájúdájú wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrètí àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa

[91] (Ẹ rántí obìnrin) èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn nínú àwọn atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá sí i lára. A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá

[92] Dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi

[93] (Àwọn yẹhudi àti nasara), wọ́n sì dá ọ̀rọ̀ (ẹ̀sìn) wọn sí kélekèle láààrin ara wọn; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) sì máa padà sí ọ̀dọ̀ Wa

[94] Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kò sí kíkọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀. Àti pé dájúdájú Àwa máa ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún un

[95] Èèwọ̀ ni fún ará ìlú kan tí A ti parẹ́ (pé kí ó tún padà sí ayé); dájúdájú wọn kò níí padà mọ́ (sí ilé ayé)

[96] (Wọn yóò wà nínú barsaku) títí A óò fi ṣí àwọn Ya’jūj àti Ma’jūj sílẹ̀. Àwọn (wọ̀nyí) yó sì máa sáré jáde láti inú gbogbo àyè gíga

[97] Àdéhùn òdodo náà súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí. Nígbà náà, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò máa ranjú kalẹ̀ ràngàndàn, (wọ́n yó sì wí pé): “Ègbé ni fún wa! Dájúdájú àwa ti wà nínú ìgbàgbéra nípa èyí. Rárá, àwa jẹ́ alábòsí ni.”

[98] Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni ìkoná Jahanamọ; ẹ̀yin yó sì wọ inú rẹ̀

[99] Tí ó bá jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí ni ọlọ́hun ni, wọn ìbá tí wọ inú Iná. Olùṣegbére sì ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú rẹ̀

[100] Iná yóò máa kùn yùn-ùn sí wọn létí; wọn kò sì níí gbọ́ (ọ̀rọ̀ mìíràn)

[101] Dájúdájú àwọn tí rere ti ṣíwájú fún láti ọ̀dọ̀ Wa, àwọn wọ̀nyẹn ni A óò gbé jìnnà sí Iná

[102] Wọn kò sì níí gbọ́ kíkùn rẹ̀. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú ìgbádùn tí ẹ̀mí wọn ń fẹ́

[103] Ìpáyà t’ó tóbi jùlọ kò níí bà wọ́n nínú jẹ́. Àwọn mọlāika yóò máa pàdé wọn, (wọn yóò sọ pé): “Èyí ni ọjọ́ yín tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín.”

[104] (Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí A máa ká sánmọ̀ bí kíká ewé tírà. Gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ (ibẹ̀ náà ni) A óò dá a padà sí. (Ó jẹ́) àdéhùn tí A ṣe. Dájúdájú Àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀

[105] Àti pé A ti kọ ọ́ sínú àwọn ìpín-ìpín Tírà (tí A sọ̀kalẹ̀) lẹ́yìn (èyí tí ó wà nínú) Tírà Ìpìlẹ̀ (ìyẹn, Laohul-Mahfūṭḥ) pé dájúdájú ilẹ̀ (Ọgbà Ìdẹ̀ra), àwọn ẹrúsìn Mi, àwọn ẹni rere, ni wọn yóò jogún rẹ̀

[106] Dájúdájú ohun t’ó tó mú ni gúnlẹ̀ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ti wà nínú (al-Ƙur’ān) yìí fún ìjọ olùjọ́sìn (fún Mi)

[107] A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá

[108] Sọ pé: “Ohun tí Wọ́n ń fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí ni pé, Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin máa di mùsùlùmí?”

[109] Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ nígbà náà pé: "Èmi ń fi to yín létí pé èmi àti ẹ̀yin dì jọ dá dúró fún ogun ẹ̀sìn (tí ó máa ṣẹlẹ̀ láààrin wa báyìí). Èmi kò sì mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín ti súnmọ́ tàbí ó sì jìnnà

[110] Dájúdájú (Allāhu) mọ ohun tí ó hàn nínú ọ̀rọ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́

[111] Èmi kò sì mọ̀ bóyá (lílọ́ yín lára) máa jẹ́ àdánwò àti ìgbádùn fun yín títí di ìgbà díẹ̀

[112] Ó sọ pé: “Olúwa mi, ṣèdájọ́ pẹ̀lú òdodo. Olúwa wa ni Àjọkẹ́-ayé, Olùrànlọ́wọ́ lórí ohun tí ẹ̀ ń fi ròyìn (Rẹ̀).”

Ìrìnàjò Hajj

Surah 22

[1] Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Dájúdájú ìmì tìtì Àkókò náà, n̄ǹkan ńlá ni

[2] (Àkókò náà ni) ọjọ́ tí ẹ máa rí i tí gbogbo obìnrin t’ó ń fún ọmọ lọ́mú mu yóò gbàgbé ọmọ tí wọ́n ń fún lọ́mú àti pé gbogbo aboyún yó sì máa bí oyún wọn. Ìwọ yó sì rí àwọn ènìyàn tí ọtí yóò máa pa wọ́n. Ọtí kò sì pa wọ́n, ṣùgbọ́n ìyà Allāhu (t’ó) le (l’ó fà á)

[3] Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni t’ó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀. Ó sì ń tẹ̀lé gbogbo èṣù olórí kunkun

[4] Wọ́n kọ ọ́ lé (Èṣù) lórí pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé e, ó máa ṣì í lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ọ sí ọ̀nà ìyà Iná t’ó ń jò fòfò

[5] Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa àjíǹde, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà láti inú bááṣí ẹran tí ó pé ní ẹ̀dá àti èyí tí kò pé ní ẹ̀dá nítorí kí A lè ṣàlàyé (agbára Wa) fun yín. A sì ń mú ohun tí A bá fẹ́ dúró sínú àpò ìbímọ títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, A óò mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (ẹ óò máa ṣẹ̀mí lọ) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Ẹni tí ó máa kú (ní kékeré) wà nínú yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí A óò dá (ìṣẹ̀mí) rẹ̀ sí di àsìkò ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ́ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Àti pé o máa rí ilẹ̀ ní gbígbẹ. Nígbà tí A bá sì sọ òjò kalẹ̀ lé e lórí, ó máa yíra padà. Ó máa gbèrú. Ó sì máa mú gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn t’ó dára jáde

[6] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[7] Àti pé dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu yóò gbé àwọn t’ó ń bẹ nínú sàréè dìde

[8] Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni t’ó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (sunnah Ànábì) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) t’ó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sọ̀rọ̀ ẹ̀sìn)

[9] Ó ń yí ọrùn rẹ̀ ká ní ti ìgbéraga nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá àwọn ènìyàn lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àbùkù ń bẹ fún un nílé ayé. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, A sì máa fún un ní ìyà Iná jónijóni tọ́ wò

[10] Ìyẹn nítorí ohun tí ọwọ́ rẹ̀ tì síwájú. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí sí àwọn ẹrúsìn Rẹ̀

[11] Ó tún wà nínú àwọn ènìyàn ẹni t’ó ń jọ́sìn fún Allāhu lórí ahọ́n. Tí rere bá ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa fi ọkàn balẹ̀ (sínú ẹ̀sìn). Tí ìfòòró bá sì ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa yíjú rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Ó ṣòfò láyé àti lọ́run. Ìyẹn ni òfò pọ́nńbélé

[12] Ó ń pè lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè kó ìnira bá a, tí kò sì lè ṣe é ní oore; ìyẹn ni ìṣìnà t’ó jìnnà (sí ìmọ̀nà)

[13] Ó ń pe ohun tí ìnira rẹ̀ súnmọ́ ju àǹfààní rẹ̀ lọ. Dájúdájú (òrìṣà) burú ní olùrànlọ́wọ́, ó sì burú ní alásùn-únmọ́

[14] Dájúdájú Allāhu yóò mú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́

[15] Ẹnikẹ́ni tí ó bá lérò pé Allāhu kò níí ran (Ànábì) lọ́wọ́ láyé àti lọ́run, kí ó na okùn sí sánmọ̀ lẹ́yìn náà kí ó gé e (ìyẹn ni pé, kí ó pokùn so). Kí ó wò ó nígbà náà bóyá ète rẹ̀ lè mú (àrànṣe) t’ó ń bínú sí kúrò (lọ́dọ̀ Ànábì s.a.w)

[16] Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní àwọn āyah t’ó yanjú. Dájúdájú Allāhu ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà

[17] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn t’ó di yẹhudi, àwọn sọ̄bi’ūn, àwọn kristiẹni, àwọn mọjūs àti àwọn t’ó ṣẹbọ, dájúdájú Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan

[18] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ni àwọn t’ó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀, àti òòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, àwọn àpáta, àwọn igi, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ń forí kanlẹ̀ fún? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì tún ni ìyà ti kò lé lórí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi àbùkù kàn, kò sí ẹnì kan tí ó máa ṣe àpọ́nlé rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́

[19] Àwọn oníjà méjì (kan) nìyí, wọ́n ń takò ara wọn nípa Olúwa wọn. Nítorí náà, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa gé aṣọ Iná fún wọn, wọ́n sì máa da omi gbígbóná lé wọn lórí láti òkè orí wọn

[20] Wọ́n máa fi yọ́ ohun tí ń bẹ nínú ikùn wọn àti awọ ara wọn

[21] Àwọn òdùrọ irin (ìyà) sì wà fún wọn pẹ̀lú

[22] Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀ látara ìbànújẹ́, wọ́n á dá wọn padà sínú rẹ̀. (A óò sọ pé): “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”

[23] Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. A óò ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà àti àlúùlúù. Aṣọ àlàárì sì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀

[24] A fún wọn ní ìmọ̀nà síbi ohun t’ó dára nínú ọ̀rọ̀. A sì tọ́ wọn sí ọ̀nà Ẹlẹ́yìn

[25] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti Mọ́sálásí Haram, èyí tí A ṣe ní dọ́gbadọ́gba fún àwọn ènìyàn, olùgbé-inú rẹ̀ àti àlejò (fún ìjọ́sìn ṣíṣe), ẹnikẹ́ni tí ó bá ní èrò láti ṣe ìyípadà kan níbẹ̀ pẹ̀lú àbòsí, A máa mú un tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò

[26] (Ẹ rántí) nígbà tí A ṣàfi hàn àyè ilé náà fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (A sì pa á láṣẹ) pé o ò gbọdọ̀ sọ kiní kan di akẹgbẹ́ fún Mi. Àti pé kí o ṣe ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, olùkírun, olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀

[27] Kí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀. Wọn yó sì máa gun àwọn ràkúnmí wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn

[28] nítorí kí wọ́n lè rí àwọn àǹfààní t’ó ń bẹ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ṣèrántí orúkọ Allāhu fún àwọn ọjọ́ tí wọ́n ti mọ̀ lórí n̄ǹkan tí Allāhu pa lésè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi bọ́ aláìlera, tálíkà

[29] Lẹ́yìn náà, kí wọ́n parí iṣẹ́ Hajj wọn, kí wọ́n mú àwọn ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kí wọ́n sì yípo Ilé Láéláé

[30] Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu fi ṣe àríṣàmì fún ẹ̀sìn ’Islām, ó lóore jùlọ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fun yín àyàfi àwọn tí wọ́n ń kà (ní èèwọ̀) fun yín. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí ẹ̀gbin òrìṣà. Kí ẹ sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ irọ́

[31] (Ẹ jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn fún Allāhu, láì níí jẹ́ ọ̀ṣẹbọ sí I. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹbọ sí Allāhu, ó dà bí ẹni t’ó jábọ́ láti ojú sánmọ̀, tí ẹyẹ sì gbé e lọ tàbí (tí) atẹ́gùn jù ú sínú àyè t’ó jìnnà

[32] Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu fi ṣe àríṣàmì fún ẹ̀sìn ’Islām, dájúdájú ó wà lára níní ìbẹ̀rù Allāhu nínú ọkàn

[33] Àwọn àǹfààní wà fun yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, Ilé Láéláé ni ibùpa àwọn ẹran náà

[34] Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ (mùsùlùmí t’ó ṣíwájú) ni A yan ẹran pípa fún nítorí kí wọ́n lè dárúkọ Allāhu lórí ohun tí Ó pèsè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Òun ni kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí fún. Kí o sì fún àwọn ọlọ́kàn ìrẹ̀lẹ̀, àwọn olùfọkànbalẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ní ìró ìdùnnú

[35] (Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá dárúkọ Allāhu (fún wọn), ọkàn wọn máa gbọ̀n rìrì. (Wọ́n jẹ́) onísùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Wọ́n jẹ́) olùkírun. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pa lésè fùn wọn

[36] Àwọn ràkúnmí, A ṣe wọ́n nínú àwọn n̄ǹkan àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu fun yín. Oore wà lára wọn fun yín. Nítorí náà, ẹ dárúkọ Allāhu lé wọn lórí (kí ẹ sì gún wọn) ní ìdúró. Nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, ẹ jẹ nínú rẹ̀. Ẹ fi bọ́ onítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti atọrọjẹ. Báyẹn ni A ṣe rọ̀ wọ́n fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)

[37] Ẹran (tí ẹ pa) àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò níí dé ọ̀dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù Allāhu láti ọ̀dọ̀ yín l’ó máa dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Báyẹn ni (Allāhu) ṣe rọ̀ wọ́n fun yín nítorí kí ẹ lè ṣe ìgbétóbi fún Allāhu nípa bí Ó ṣe fi ọ̀nà mọ̀ yín. Kí o sì fún àwọn olùṣe-rere ní ìró ìdùnnú

[38] Dájúdájú Allāhu ń ti aburú kúrò fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn oníjàǹbá, aláìgbàgbọ́

[39] A yọ̀ǹda (ogun ẹ̀sìn jíjà) fún àwọn (mùsùlùmí) tí (àwọn kèfèrí) ń gbógun tì nítorí pé (àwọn kèfèrí) ti ṣe àbòsí sí wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí àrànṣe wọn

[40] (Àwọn ni) àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ilé wọn ní ọ̀nà àìtọ́ àfi (nítorí pé) wọ́n ń sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, wọn ìbá ti wó ilé ìsìn àwọn fadá, ṣọ́ọ̀ṣì, sínágọ́gù àti àwọn mọ́sálásí tí wọ́n ti ń dárúkọ Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.1 Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni t’ó ń ran (ẹ̀sìn ’Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí

[41] (Àwọn náà ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá fún wọn ní ipò lórí ilẹ̀, wọn yóò kírun, wọn yóò yọ Zakāh, wọn yóò pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì kọ ohun burúkú. Ti Allāhu sì ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá

[42] Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti ìjọ Thamūd kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ wọn ní òpùrọ́ ṣíwájú wọn

[43] Àti pé ìjọ ’Ibrọhīm àti ìjọ (Ànábì) Lūt

[44] àti àwọn ará ìlú Mọdyan (àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀). Wọ́n tún pe (Ànábì) Mūsā ní òpùrọ́. Mo sì lọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí

[45] Nítorí náà, mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí; àwọn ilé wọn dàwó lulẹ̀ pẹ̀lú òrùlé rẹ̀. (Mélòó mélòó nínú) kànǹga tí wọ́n ti patì (nípasẹ̀ ìparun) àti ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì oníbíríkì (t’ó ti dahoro)

[46] Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n sì ní àwọn ọkàn tí wọ́n máa fi ṣe làákàyè tàbí àwọn etí tí wọn máa fi gbọ́rọ̀? Dájúdájú àwọn ojú kò fọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọkàn t’ó wà nínú igbá-àyà l’ó ń fọ́

[47] Wọ́n sì ń kán ọ lójú fún ìyà náà. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Dájúdájú ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún nínú ohun tí ẹ̀ ń kà (ní òǹkà). Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa ìdí tí ìyà kò fi tètè sọ̀kalẹ̀ lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí pé tí Òun bá sọ fún wọn pé àárọ̀ ọ̀la ni ọjọ́ ìyà wọn (bí àpẹẹrẹ) dípò ẹgbẹ̀rún ọdún. Kíyè sí i nínú āyah ọjọ́ kan ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún ó tún lè jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún yálà nílé yìí tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde

[48] Mélòó mélòó nínú ìlú tí Mo lọ́ lára, tí wọ́n jẹ́ alábòsí. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[49] Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, èmi mà ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín

[50] Nítorí náà, àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn

[51] Àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ burúkú nípa àwọn āyah Wa, (tí wọ́n lérò pé) àwọn mórí bọ́ nínú ìyà; àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm

[52] A kò rán Òjíṣẹ́ kan tàbí Ànábì kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, Èṣù máa ju (n̄ǹkan) sínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu yóò pa ohun tí Èṣù ń jù sínú rẹ̀ rẹ́. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo àwọn āyah Rẹ̀ rinlẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. wọn kò ní ìmọ̀ olóóókan nípa al-Ƙur’ān àti hadīth ṣùgbọ́n wọ́n mọ irọ́ funfun báláú pa mọ́ ẹ̀sìn ’Islām. Ìṣe wọn yìí sì ṣe wẹ́kú ọ̀rọ̀ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú sūrah al-Baƙọrah; 2: 78. ẹni tí Èṣù bá ń gbẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ bí kò jẹ́ wèrè tí kò ṣe é fi ṣe ẹ̀rí àfi hadīth ẹyọ kan péré. Ìyẹn ni pé gbogbo hadīth t’ó ń sọ nípa pé Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé “Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹyẹ àgbà. Àti pé ìrètí wà nínú ìṣìpẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.” jẹ́ hadīth t’ó lẹ pátápátá. Àmọ́ èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú wọn kò tayọ èyí tí ó wà nínú sọhīhu-l-Bukọ̄riy ẹ̀gbàwá Bukọ̄riy ti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Kò sì sí ọ̀rọ̀ “àwọn ẹyẹ àgbà mẹ́ta” kan kan nínú rẹ̀. Nítorí náà hadīth kò báà lé ní igba lórí ọ̀rọ̀ kan náà

[53] (Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè fi ohun tí Èṣù ń jù (sínú rẹ̀) ṣe àdánwò fún àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn tí ọkàn wọn le. Dájúdájú àwọn alábòsí sì wà nínú ìyapa t’ó jìnnà (sí òdodo)

[54] (Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní ìmọ̀ lè mọ̀ pé dájúdájú al- Ƙur’ān jẹ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, wọn yó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, ọkàn wọn yó sì balẹ̀ sí i. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fi ẹsẹ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām)

[55] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kò sì níí yé wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ títí Àkókò náà yóò fi dé bá wọn ní òjijì tàbí (títí) ìyà ọjọ́ ìparun yóò fi dé bá wọn

[56] Gbogbo ìjọba ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Allāhu tí Ó máa ṣèdájọ́ láààrin wọn. Nítorí náà, àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

[57] Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa nírọ́; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún

[58] Àwọn tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, lẹ́yìn náà, tí wọ́n pa wọ́n tàbí tí wọ́n kú; dájúdájú Allāhu yóò pèsè fún wọn ní ìpèsè t’ó dára. Dájúdájú Allāhu, Ó mà l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè

[59] Dájúdájú (Allāhu) yóò fi wọ́n sí àyè kan tí wọn yóò yọ́nú sí. Dájúdájú Allāhu mà ni Onímọ̀, Aláfaradà

[60] Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, lẹ́yìn náà tí wọ́n bá tún ṣàbòsí sí i, dájúdájú Allāhu yóò ṣàrànṣe fún un. Dájúdájú Allāhu mà ni Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn

[61] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ń fi òru bọ inú ọ̀sán, Ó sì ń fi ọ̀sán bọ inú òru. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Olùríran

[62] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi

[63] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, ilẹ̀ sì máa lọ́ràá wá? Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán

[64] TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun mà ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́

[65] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ fun yín, àti ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn nínú agbami odò pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀, Ó ń mú sánmọ̀ dání tí kò fi jábọ́ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Dájúdájú Allāhu mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn

[66] Òun sì ni Ẹni t’Ó ṣe yín ni alààyè, lẹ́yìn náà Ó ń sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà Ó máa sọ yín di alààyè. Dájúdájú ènìyàn mà ni aláìmoore

[67] Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe jà ọ́ níyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Kí o sì pèpè sọ́dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú o kúkú wà lójú ọ̀nà tààrà

[68] Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ nígbà náà pé: "Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[69] Allāhu máa ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí

[70] Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu

[71] Dípò (kí wọ́n jọ́sìn fún) Allāhu, wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí (Allāhu) kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún àti ohun tí kò sí ìmọ̀ kan fún wọn lórí rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí

[72] Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, o máa rí ìkorò-ojú nínú ojú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́; wọn yó sì fẹ́ẹ̀ fọwọ́ ìnira kan àwọn tí ń ké àwọn āyah Wa fún wọn. Sọ pé: "Ṣé kí n̄g fun yín ní ìró ohun t’ó burú ju ìyẹn? Iná tí Allāhu ṣèlérí rẹ̀ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ni. Ìkángun náà sì burú

[73] Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi àkàwé kan lélẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ́tí sí i. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, wọn kò lè dá eṣinṣin kan, wọn ìbàá para pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tí eṣinṣin bá sì gba kiní kan mọ́ wọn lọ́wọ́, wọn kò lè gbà á padà lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀lẹ ni ẹni tí ń wá n̄ǹkan (lọ́dọ̀ òrìṣà) àti (òrìṣà) tí wọ́n ń wá n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀

[74] Wọn kò bu ọ̀wọ̀ fún Allāhu ní ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí I. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí

[75] Allāhu l’Ó ń ṣa àwọn kan lẹ́ṣà (láti jẹ́) Òjíṣẹ́ nínú àwọn mọlāika àti nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran

[76] Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí

[77] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ dáwọ́ tẹ orúnkún (lórí ìrun), ẹ forí kanlẹ̀, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, kí ẹ sì ṣe rere nítorí kí ẹ lè jèrè

[78] Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l’Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe

Àwọn Onígbàgbọ́ Òdodo

Surah 23

[1] Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè

[2] Àwọn t’ó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn

[3] àti àwọn t’ó ń ṣẹ́rí kúrò níbi ìsọkúsọ

[4] àti àwọn t’ó ń yọ Zakāh

[5] àti àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn

[6] àfi ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó wọn àti ẹrúbìnrin wọn. Dájúdájú wọn kì í ṣe ẹni èébú (tí wọ́n bá súnmọ́ wọn)

[7] nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wá òmíràn (súnmọ́) lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ ẹnu-àlà

[8] àti àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn

[9] àti àwọn t’ó ń ṣọ́ ìrun wọn

[10] àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùjogún

[11] àwọn t’ó máa jogún ọgbà ìdẹ̀ra Firdaos. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀

[12] Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú erùpẹ̀ amọ̀

[13] Lẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)

[14] Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.1 Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà)

[15] Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yó sì di òkú

[16] Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde Wọ́n máa gbe yín dìde

[17] Dájúdájú A dá àwọn sánmọ̀ méje sí òkè yín. Àwa kò sì níí dágunlá sí àwọn ẹ̀dá

[18] À ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n níwọ̀n. Lẹ́yìn náà, À ń mú un dúró sínú ilẹ̀. Dájúdájú Àwa kúkú lágbára láti mú un lọ

[19] Lẹ́yìn náà, A dá àwọn ọgbà oko dàbínù àti àjàrà fun yín; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso wà nínú rẹ̀ fun yín, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀

[20] Àti igi kan t’ó ń hù jáde níbi àpáta Sīnā’; ó ń mú epo àti n̄ǹkan ìṣebẹ̀ jáde fún àwọn t’ó ń jẹ ẹ́

[21] Àti pé dájúdájú àríwòye wà fun yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn; À ń fun yín mu nínú ohun tí ó wà nínú ikùn wọn. Àwọn àǹfààní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (mìíràn) tún wà fun yín lára wọn, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀

[22] Ẹ sì ń kó ẹrù sí orí àwọn ẹran ọ̀sìn àti ọkọ̀ ojú-omi

[23] Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”

[24] Àwọn olórí tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín, tí ó fẹ́ gbé àjùlọ fún ara rẹ̀ lórí yín. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ránṣẹ́ sí wa ni), ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ ni. A kò sì gbọ́ èyí rí lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́

[25] Kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí (ìkángun) rẹ̀ títí di ìgbà kan ná.”

[26] (Ànábì) Nūh sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́

[27] Nítorí náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: "Ṣe ọkọ̀ ojú-omi ní ojú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Nígbà tí àṣẹ Wa bá dé, tí omi bá ṣẹ́ yọ ní ojú àrò, nígbà náà ni kí o kó sínú ọkọ̀ ojú-omi gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ, àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí nínú wọn (fún ìparun). Má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó ṣàbòsí; dájúdájú A óò tẹ̀ wọ́n rì sínú omi ni

[28] Nígbà tí o bá jókòó sínú ọkọ̀ ojú-omi náà, ìwọ àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ, sọ pé: 'Ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ẹni tí Ó gbà wá là lọ́wọ́ ijọ alábòsí

[29] Sọ pé: “Olúwa mi, sọ̀ mí kalẹ̀ sí ibùsọ̀ ìbùkún. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn amúnigúnlẹ̀.”

[30] Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Àwa sì ni À ń dán ẹ̀dá wò

[31] Lẹ́yìn náà, A mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn

[32] A tún rán Òjíṣẹ́ kan sí wọn láààrin ara wọn (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”

[33] Àwọn olórí t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀, àwọn t’ó pe ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn tí A ṣe gbẹdẹmukẹ fún nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, wọ́n wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín; ó ń jẹ nínú ohun tí ẹ̀ ń jẹ, ó sì ń mu nínú ohun tí ẹ̀ ń mu

[34] Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé abara kan bí irú yín, dájúdájú ẹ mà ti di ẹni òfò nìyẹn

[35] Ṣé ó ń ṣe àdéhùn fun yín pé nígbà tí ẹ bá kú, tí ẹ sì di erùpẹ̀ àti egungun tán, dájúdájú Wọn yóò mu yín jáde (ní alààyè)

[36] Ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín (yìí) jìnnà tefétefé (sí òdodo)

[37] Kò sí ìṣẹ̀mí ayé kan mọ́ àyàfi èyí tí à ń lò yìí; àwa kan ń kú, àwa kan ń wáyé. Kò sì sí pé Wọn yóò gbé wa dìde mọ́

[38] (Òjíṣẹ́ náà) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Àwa kò sì níí gbà á gbọ́

[39] (Òjíṣẹ́ náà) sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́

[40] (Allāhu) sọ pé: “Láìpẹ́ ńṣe ni wọn yóò di alábàámọ̀.”

[41] Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn lọ́nà ẹ̀tọ́. A sì sọ wọ́n di pàǹtí. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ alábòsí

[42] Lẹ́yìn náà, A tún mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn

[43] Ìjọ kan kò níí lọ ṣíwájú àkókò (ìparun) rẹ̀, wọn kò sì níí sún (ìparun wọn) síwájú

[44] Lẹ́yìn náà, A rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ ìjọ kan bá dé, wọ́n ń pè é ní òpùrọ́. A sì mú apá kan wọn tẹ̀lé apá kan nínú ìparun. A tún sọ wọ́n di ìtàn. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ tí kò gbàgbọ́ lódodo

[45] Lẹ́yìn náà, A rán (Ànábì) Mūsā àti ọmọ-ìyá rẹ̀ (Ànábì) Hārūn níṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé

[46] (A rán wọn níṣẹ́) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣègbéraga, wọ́n sì jẹ́ ìjọ olùjẹgàba

[47] Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gba abara méjì bí irú wa gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹrú wa ni àwọn ènìyàn wọn?”

[48] Nítorí náà, wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. Wọ́n sì wà nínú àwọn ẹni- ìparun

[49] Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà

[50] A ṣe ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ ní àmì kan. A sì ṣe ibùgbé fún àwọn méjèèjì sí ibi gíga kan, t’ó ní ibùgbé, t’ó sì ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú

[51] Ẹ̀yin Òjíṣẹ́, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú Èmi ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[52] Àti pé dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi

[53] Ṣùgbọ́n wọ́n gé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn láààrin ara wọn sí kélekèle. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun t’ó ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wọn

[54] Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìṣìnà wọn títí di ìgbà kan ná

[55] Ṣé wọ́n ń lérò pé (bí) A ṣe ń fi dúkìá àti ọmọ nìkan ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn

[56] ni A óò ṣe máa yára ti àwọn oore sí ọ̀dọ̀ wọn lọ (títí láéláé). Rárá, wọn kò fura ni

[57] Dájúdájú àwọn t’ó ń páyà (ìṣírò-iṣẹ́) fún ìpáyà wọn nínú Olúwa wọn

[58] àti àwọn t’ó ń gba àwọn āyah Olúwa wọn gbọ́

[59] àti àwọn tí kì í ṣẹbọ sí Olúwa wọn

[60] àti àwọn t’ó ń ṣe ohun rere (nínú iṣẹ́) tí wọ́n ṣe, pẹ̀lú ìbẹ̀rù nínú ọkàn wọn pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn

[61] àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ń yára ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn sì ni aṣíwájú nínú (àwọn ẹ̀san) iṣẹ́ náà

[62] Àti pé A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tírà kan t’ó ń sọ òdodo (nípa iṣẹ́ ẹ̀dá) ń bẹ lọ́dọ̀ Wa. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[63] Àmọ́ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ wà nínú ìfọ́núfọ́ra nípa (al-Ƙur’ān) yìí. Àti pé wọ́n ní àwọn iṣẹ́ kan lọ́wọ́, tí ó yàtọ̀ sí iṣẹ́ rere yẹn. Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ náà

[64] títí di ìgbà tí A máa gbá àwọn onígbẹdẹmukẹ nínú wọn mú pẹ̀lú ìyà. Nígbà náà ni wọ́n máa ké gbàjarì

[65] Ẹ má kèé gbàjarì lónìí. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lọ́dọ̀ Wa

[66] Wọ́n kúkú ń ka àwọn āyah Mi fun yín. Àmọ́ ńṣe ni ẹ̀ ń fà sẹ́yìn (níbi òdodo)

[67] Ẹ̀ sì ń fi Kaaba ṣègbéraga, ẹ tún ń fi òru yín sọ ìsọkúsọ (nípa al-Ƙur’ān)

[68] Ṣé wọn kò ronú sí ọ̀rọ̀ náà ni? Tàbí ohun t’ó dé bá wọn jẹ́ ohun tí kò dé bá àwọn bàbá wọn àkọ́kọ́ rí ni

[69] Tàbí wọn kò mọ Òjíṣẹ́ wọn mọ́ ni wọ́n fi di alátakò rẹ̀

[70] Tàbí wọn ń wí pé àlùjànnú kan ń bẹ lára rẹ̀ ni? Rárá o. Ó mú òdodo wá bá wọn ni. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì jẹ́ olùkórira òdodo

[71] Tí ó bá jẹ́ pé (Allāhu), Ọba Òdodo tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni, àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àwọn t’ó wà nínú wọn ìbá kúkú ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n A mú ìṣítí nípa ọ̀rọ̀ ara wọn wá fún wọn ni, wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbi ìṣítí (tí A mú wá fún) wọn

[72] Tàbí ò ń béèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn ni? Owó-ọ̀yà Olúwa rẹ̀ lóore jùlọ. Àti pé Òun l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè

[73] Àti pé dájúdájú ò ń pè wọ́n sójú ọ̀nà tààrà ni

[74] Àwọn tí kò sì gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ni wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò lójú ọ̀nà náà

[75] Tí ó bá jẹ́ pé A kẹ́ wọn (nílé ayé), tí A sì gbé gbogbo ìṣòro ara wọn kúrò fún wọn, wọn ìbá tún won̄koko mọ́ ìtayọ ẹnu-àlà wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà (nínú ìṣìnà)

[76] Dájúdájú A fi ìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọn kò tẹríba fún Olúwa wọn, wọn kò sì rawọ́ rasẹ̀ sí I

[77] títí di ìgbà tí A fi ṣílẹ̀kùn ìyà líle fún wọn; nígbà náà ni wọ́n sọ̀rètí nù

[78] (Allāhu), Òun ni Ẹni tí Ó ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fun yín, ìdúpẹ́ yín sì kéré

[79] Òun ni Ẹni tí Ó da yín sórí ilẹ̀, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n yóò ko yín jọ sí

[80] Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè, Ó ń sọ ẹ̀dá di òkú, tiRẹ̀ sì ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni

[81] Rárá (wọn kò níí ṣe làákàyè, ṣebí) irú ohun tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wí ni àwọn náà wí

[82] Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé wọn yóò gbé wa dìde ni

[83] Wọ́n kúkú ti ṣe àdéhùn yìí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

[84] Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti ẹni tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”

[85] Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?”

[86] Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?”

[87] Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”

[88] Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?” Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”

[89] Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?”

[90] Àmọ́ sá, òdodo ni A mú wá ba wọn. Dájúdájú àwọn sì ni òpùrọ́

[91] Allāhu kò fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ, kò sì sí ọlọ́hun kan pẹ̀lú Rẹ̀. (Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ọlọ́hun kọ̀ọ̀kan ìbá ti kó ẹ̀dá t’ó dá lọ, apá kan wọn ìbá sì borí apá kan. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀ nípa ọmọ bíbí)

[92] (Allāhu) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nítorí náà, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I

[93] Sọ pé: “Olúwa mi, Ó ṣeé ṣe kí Ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn hàn mí

[94] Olúwa mi, má ṣe fi mí sínú ìjọ alábòsí.”

[95] Dájúdájú Àwa lágbára láti fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́

[96] Fi èyí t’ó dára tí àìdára dànù. Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n fi ń ròyìn (Wa)

[97] Sọ pé: "Olúwa mi, mò ń sádi Ọ́ níbi ròyíròyí t’àwọn èṣù

[98] Mò ń sádi Ọ́, Olúwa mi, níbi kí wọ́n wá bá mi

[99] (Wọ́n ń ṣẹ̀mí lọ) títí di ìgbà tí ikú fi máa dé bá ọ̀kan nínú wọn. Ó sì máa wí pé: “Olúwa mi, Ẹ dá mi padà (sílé ayé)

[100] nítorí kí n̄g lè ṣe iṣẹ́ rere nínú èyí tí mo gbé jù sílẹ̀. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, dájúdájú ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn ń wí ni, (àmọ́) gàgá ti wà ní ẹ̀yìn wọn títí di ọjọ́ tí A óò gbé wọn dìde. ayẹta òkígbẹ́

[101] Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, kò níí sí ìbátan láààrin wọn ní ọjọ́ yẹn, wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè

[102] Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè

[103] Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú iná Jahanamọ

[104] Iná yóò máa jó wọn lójú. Wọn yó sì wà nínú rẹ̀, tí Iná yóò ti bà wọ́n lójú jẹ́

[105] Ṣé wọ́n kì í ka àwọn āyah Mi fun yín ni, àmọ́ tí ẹ̀ ń pè é nírọ́

[106] Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, orí burúkú l’ó kọlù wá; àwa sì jẹ́ ìjọ olùṣìnà

[107] Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú Iná. Tí a bá fi lè padà (síbi iṣẹ́ ibi nílé ayé), dájúdájú nígbà náà alábòsí ni àwa

[108] (Allāhu) sọ pé: “Ẹ tẹ̀rì sínú rẹ̀. Ẹ má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀.”

[109] Dájúdájú igun kan wà nínú àwọn ẹrúsìn Mi, tí wọ́n ń sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

[110] Ṣùgbọ́n ẹ sọ wọ́n di oníyẹ̀yẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn yẹ̀yẹ́ (yín) fi mu yín gbàgbé ìrántí Mi. Ẹ̀yin sì ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín

[111] Dájúdájú Mo san wọ́n ní ẹ̀san ní òní nítorí sùúrù wọn; dájúdájú àwọn, àwọn ni olùjèrè

[112] (Allāhu) sọ pé: "Ọdún mélòó ni ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) lò lórí ilẹ̀ ayé

[113] Wọ́n wí pé: “A lo ọjọ́ kan tàbí abala ọjọ́ kan, bi àwọn olùṣírò-ọjọ́ léèrè wò.”

[114] (Allāhu) sọ pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”

[115] Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?”

[116] Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé

[117] Ẹni tí ó bá pe ọlọ́hun mìíràn pẹ̀lú Allāhu, kò ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí rẹ̀. Dájúdájú ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́ kò níí jèrè

[118] Sọ pé: “Olúwa mi, ṣàforíjìn, kí O sì kẹ́ (mi). Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

Ìmọ́lẹ̀

Surah 24

[1] (Èyí ni) Sūrah kan tí A sọ̀kalẹ̀. A ṣe é ní òfin. A sì sọ àwọn āyah t’ó yanjú kalẹ̀ sínú rẹ̀ nítorí kí ẹ lè lo ìrántí

[2] Onísìná lóbìnrin àti onísìná lọ́kùnrin, ẹ na ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ní ọgọ́rùn-ún kòbókò. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àánú wọn ṣe yín nípa ìdájọ́ Allāhu tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kí igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo sì jẹ́rìí sí ìyà àwọn méjèèjì. tí ó bá di oyún tí ọkọ rẹ̀ kò sì mọ̀ wọn kò níí fún wọn lẹ́tọ̀ọ́ sí oorun ìfẹ́ mìíràn mọ́ torí pé kò sí ìtakókó yìgì láààrin wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí nínú àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn t’ó ní wọ́n lè ṣe ìtakókó yìgì obìnrin náà fún arákùnrin t’ó ṣe zinā pẹ̀lú rẹ̀ lórí oyún zinā náà nítorí kí wọ́n lè máa jẹ ìgbádùn ara wọn lọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ èyí tí ó dára jùlọ ni pé

[3] Onísìná lọ́kùnrin kò níí ṣe sìná pẹ̀lú ẹnì kan bí kò ṣe onísìná lóbìnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin. Onísìná lóbìnrin, ẹnì kan kò níí bá a ṣe sìná bí kò ṣe onísìná lọ́kùnrin (ẹgbẹ́ rẹ̀) tàbí ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin. A sì ṣe ìyẹn ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[4] Àwọn t’ó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ọmọlúàbí lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò mú àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá, ẹ nà wọ́n ní ọgọ́rin kòbókò. Ẹ má ṣe gba ẹ̀rí wọn mọ́ láéláé; àwọn wọ̀nyẹn sì ni òbìlẹ̀jẹ́

[5] Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[6] Àwọn t’ó ń fi ẹ̀sùn sìná kan àwọn ìyàwó wọn, tí kò sì sí ẹlẹ́rìí fún wọn àfi àwọn fúnra wọn, ẹ̀rí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú òun wà nínú àwọn olódodo

[7] Ẹ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ibi dandan Allāhu máa bá òun, tí òun bá wà nínú àwọn òpùrọ́

[8] Ohun tí ó máa yẹ ìyà fún ìyàwó ni pé kí ó fi Allāhu jẹ́rìí ní ẹ̀ẹ̀ mẹrin pé dájúdájú ọkọ òun wà nínú àwọn òpùrọ́

[9] Ẹ̀ẹ̀ karùn-ún sì ni pé kí ìbínú Allāhu máa bá òun, tí ọkọ òun bá wà nínú àwọn olódodo

[10] Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá máa tú àṣírí yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Ọlọ́gbọ́n

[11] Dájúdájú àwọn t’ó mú àdápa irọ́ wá jẹ́ ìjọ kan nínú yín. Ẹ má ṣe lérò pé aburú ni fun yín. Rárá o, oore ni fun yín. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ti ní ohun tí ó dá ní ẹ̀ṣẹ̀. Àti pé ẹni tí ó dá (ẹ̀ṣẹ̀) jùlọ nínú wọn, ìyà ńlá ni tirẹ̀

[12] Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin ro dáadáa rora wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Èyí ni àdápa irọ́ pọ́nńbélé.”

[13] Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹlẹ́rìí mẹ́rin wá lórí rẹ̀? Nítorí náà, nígbà tí wọn kò ti mú àwọn ẹlẹ́rìí wá, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òpùrọ́ lọ́dọ̀ Allāhu

[14] Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ní ilé ayé àti ní ọ̀run ni, dájúdájú ìyà ńlá ìbá fọwọ́ bà yín nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ kiri ní ìsọkúsọ

[15] (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gbà á (láààrin ara yín) pẹ̀lú ahọ́n yín, tí ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀; ẹ lérò pé n̄ǹkan t’ó fúyẹ́ ni, n̄ǹkan ńlá sì ni lọ́dọ̀ Allāhu

[16] Nígbà tí ẹ gbọ́ ọ, kí ni kò jẹ́ kí ẹ sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀tọ́ fún wa pé kí á sọ èyí. Mímọ́ ni fún Ọ (Allāhu)! Èyí ni ìparọ́-mọ́ni t’ó tóbi.”

[17] Allāhu ń ṣe wáàsí fun yín pé kí ẹ má ṣe padà síbi irú rẹ̀ mọ́ láéláé tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[18] Allāhu ń ṣàlàyé àwọn āyah náà. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[19] Dájúdájú àwọn t’ó nífẹ̀ẹ́ sí kí (ọ̀rọ̀) ìbàjẹ́ máa tàn kálẹ̀ nípa àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀

[20] Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni (Allāhu ìbá tètè fìyà jẹ yín ni). Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[21] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù, dájúdájú (Èṣù) yóò pàṣẹ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú (fún un). Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti ìkẹ́ Rẹ̀ lórí yín ni, ẹnì kan ìbá tí mọ́ nínú yín láéláé. Ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[22] Kí àwọn t’ó ní ọlá àti ìgbàláàyè nínú yín má ṣe búra pé àwọn kò níí ṣe dáadáa sí àwọn ìbátan, àwọn mẹ̀kúnnù àti àwọn t’ó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu. Kí wọ́n ṣàforíjìn, kí wọ́n sì ṣàmójúkúrò. Ṣé ẹ ò fẹ́ kí Allāhu foríjìn yín ni? Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[23] Dájúdájú àwọn t’ó ń parọ́ sìná mọ́ àwọn ọmọlúàbí l’óbìnrin, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, A ti ṣẹ́bi lé wọn ní ayé àti ní ọ̀run. Ìyà ńlá sì wà fún wọn

[24] Ní ọjọ́ tí àwọn ahọ́n wọn, ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn yóò máa jẹ́rìí takò wọ́n nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[25] ní ọjọ́ yẹn ni Allāhu yóò san wọ́n ní ẹ̀san wọn tí ó tọ́ sí wọn. Wọn yó sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo pọ́nńbélé

[26] Àwọn obìnrin burúkú wà fún àwọn ọkùnrin burúkú. Àwọn ọkùnrin burúkú sì wà fún àwọn obìnrin burúkú. Àwọn obìnrin rere wà fún àwọn ọkùnrin rere. Àwọn ọkùnrin rere sì wà fún àwọn obìnrin rere. Àwọn (ẹni rere) wọ̀nyí mọ́wọ́-mọ́sẹ̀ nínú (àìdaa) tí wọ́n ń sọ sí wọn. Àforíjìn àti èsè alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn

[27] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe wọ àwọn ilé kan yàtọ̀ sí àwọn ilé yín títí ẹ máa fi tọrọ ìyọ̀ǹda àti (títí) ẹ máa fi sálámọ̀ sí àwọn ará inú ilé náà. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí

[28] Tí ẹ ò bá sì bá ẹnì kan kan nínú ilé náà, ẹ má ṣe wọ inú rẹ̀ títí wọn yóò fi yọ̀ǹda fun yín. Tí wọ́n bá sì sọ fun yín pé kí ẹ padà, nítorí náà ẹ padà. Òhun l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[29] Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín láti wọ inú àwọn ilé kan tí kì í ṣe ibùgbé, tí àǹfààní wà nínú rẹ̀ fun yín . Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́

[30] Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Ìyẹn fọ̀ wọ́n mọ́ jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[31] Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Kí wọ́n má ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀.1 Kí wọ́n fi ìbòrí wọn bo igbá-àyà wọn.2 Àti pé kí wọ́n má ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi fún àwọn ọkọ wọn tàbí àwọn bàbá wọn tàbí àwọn bàbá ọkọ wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin ọkọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn tàbí àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn tàbí àwọn ẹrúkùnrin wọn tàbí àwọn t’ó ń tẹ̀lé obìnrin fún iṣẹ́ rírán, tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin akúra tàbí àwọn ọmọdé tí kò tí ì dá ìhòhò àwọn obìnrin mọ̀ (sí n̄ǹkan kan). Kí wọ́n má ṣe fi ẹsẹ̀ wọn rin ìrìn-kokokà nítorí kí àwọn (ènìyàn) lè mọ ohun tí wọ́n fi pamọ́ (sára) nínú ọ̀ṣọ́ wọn. Kí gbogbo yín sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí ẹ lè jèrè

[32] Ẹ fi ìyàwó fún àwọn àpọ́n nínú yín àti àwọn ẹni ire nínú àwọn ẹrúkùnrin yín. (Kí ẹ sì wá ọkọ rere fún) àwọn ẹrúbìnrin yín. Tí wọ́n bá jẹ́ aláìní, Allāhu yóò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Allāhu sì ni Olùgbààye, Onímọ̀

[33] Kí àwọn tí kò rí (owó láti fẹ́) ìyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.1 Àwọn t’ó ń wá ìwé òmìnira nínú àwọn ẹrú yín, ẹ kọ ìwé òmìnira fún wọn tí ẹ bá mọ ohun rere nípa wọn. Kí ẹ sì fún wọn nínú dúkìá Allāhu tí Ó fun yín. (Nítorí dúkìá ayé tí ẹ̀ ń wá), ẹ má ṣe jẹ àwọn ẹrúbìnrin yín nípá láti lọ ṣe sìná, tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ wọ́n nípá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ wọ́n nípá

[34] Dájúdájú A ti sọ àwọn àmì t’ó yanjú, ìtàn àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú yín àti wáàsí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) kalẹ̀ fun yín

[35] Allāhu ni Olùtan-ìmọ́lẹ̀ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àpèjúwe ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ dà bí òpó àtùpà kan tí àtùpà wà nínú rẹ̀. Àtùpà náà sì wà nínú díńgí. Díńgí náà dà bí ìràwọ̀ kan t’ó ń tàn yànrànyànràn. Wọ́n ń tan (ìmọ́lẹ̀ náà) láti ara igi ìbùkún kan, igi zaetūn. Kì í gba ìmọ́lẹ̀ nígbà tí òòrùn bá ń yọ jáde tàbí nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀. Epo (ìmọ́lẹ̀) rẹ̀ fẹ́ẹ̀ dá mú ìmọ́lẹ̀ wá, iná ìbáà má dé ibẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ lórí ìmọ́lẹ̀ ni. Allāhu ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí (ọ̀nà) ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Allāhu ń fi àwọn àkàwé lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[36] (Àwọn àtùpà ìbùkún náà wà) nínú àwọn ilé kan (ìyẹn àwọn mọ́sálásí) èyí tí Allāhu yọ̀ǹda pé kí wọ́n gbéga,1 kí wọ́n sì máa dárúkọ Rẹ̀ nínú rẹ̀. (Àwọn ènìyàn) yó sì máa ṣàfọ̀mọ́ fún Un nínú rẹ̀ ní àárọ̀ àti àṣálẹ́

[37] Àwọn ọkùnrin tí òwò àti kárà-kátà kò dí lọ́wọ́ níbi ìrántí Allāhu, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ, àwọn t’ó ń páyà ọjọ́ kan tí àwọn ọkàn àti ojú yóò máa yí sí ọ̀tún yí sí òsì

[38] (Wọ́n ṣe rere wọ̀nyí) nítorí kí Allāhu lè fi èyí t’ó dára nínú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san rere àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Àti pé Allāhu ń pèsè arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì la ìṣírò lọ

[39] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ wọn dà bí ahúnpeéná t’ó wà ní pápá, tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ sì lérò pé omi ni títí di ìgbà tí ó dé síbẹ̀, kò sì bá kiní kan níbẹ̀. Ó sì bá Allāhu níbi (iṣẹ́) rẹ̀ (ní ọ̀run). (Allāhu) sì ṣe àṣepé ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ fún un. Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́

[40] Tàbí (iṣẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́) dà bí àwọn òkùnkùn kan nínú ibúdò jíjìn, tí ìgbì omi ń bò ó mọ́lẹ̀, tí ìgbì omi mìíràn tún wà ní òkè rẹ̀, tí ẹ̀ṣújò sì wà ní òkè rẹ̀; àwọn òkùnkùn biribiri tí apá kan wọ́n wà lórí apá kan (nìyí). Nígbà tí ó bá nawọ́ ara rẹ̀ jáde, kò ní fẹ́ẹ̀ rí i. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu kò bá fún ní ìmọ́lẹ̀, kò lè sí ìmọ́lẹ̀ kan fún un

[41] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ni gbogbo ẹni t’ó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún? Àwọn ẹyẹ náà (ń ṣe bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n bá ń na ìyẹ́ apá wọn? Ìkọ̀ọ̀kan wọn kúkú ti mọ bí ó ṣe máa kírun rẹ̀ àti bí ó ṣe máa ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ (fún Un). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[42] Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[43] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ń da ẹ̀ṣújò káàkiri ni? Lẹ́yìn náà Ó ń kó o jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbé wọn gun ara wọn, nígbà náà ni o máa rí òjò tí ó máa jáde láti ààrin rẹ̀. Láti inú sánmọ̀, Ó sì ń sọ àwọn yìyín kan (t’ó dà bí) àwọn àpáta kalẹ̀ sí orí ilẹ̀ ayé. Ó ń mú un kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Kíkọ yànrànyànràn mọ̀nàmọ́ná inú ẹ̀ṣújò sì fẹ́ẹ̀ lè fọ́ àwọn ojú

[44] Allāhu ń mú òru àti ọ̀sán tẹ̀lé ara wọn ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn t’ó ní ojú ìríran

[45] Allāhu ṣẹ̀dá gbogbo abẹ̀mí láti inú omi. Ó wà nínú wọn, èyí t’ó ń fi àyà rẹ̀ wọ́. Ó wà nínú wọn, èyí t’ó ń fi ẹsẹ̀ méjì rìn. Ó sì wà nínú wọn, èyí t’ó ń fi mẹ́rin rìn. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[46] Dájúdájú A ti sọ àwọn āyah t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ kalẹ̀. Allāhu sì ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām)

[47] Wọ́n ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A sì tẹ̀lé (àṣẹ Wọn).” Lẹ́yìn náà, igun kan nínú wọn ń pẹ̀yìn dà lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn wọ̀nyẹn kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo

[48] Àti pé nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa gbúnrí

[49] Tí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ni wọ́n ni ẹ̀tọ́ (àre) ni, wọn yóò wá bá ọ ní tọkàn-tara

[50] Ṣé àrùn wà nínú ọkàn wọn ni tàbí wọ́n ṣeyèméjì? Tàbí wọ́n ń páyà pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yóò fi ẹjọ́ wọn ṣègbè ni? Rárá o. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí

[51] Ohun tí ó máa jẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n bá pè wọ́n sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèdájọ́ láààrin wọn, ni pé wọ́n á sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ).” Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè

[52] Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó ń páyà Allāhu, tí ó sì ń bẹ̀rù Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè

[53] Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbura wọn sì ní agbára pé: "Dájúdájú tí o bá pàṣẹ fún àwọn, dájúdájú àwọn yóò jáde." Sọ pé: “Ẹ má ṣe búra mọ́. Títẹ̀lé àṣẹ (pẹ̀lú ìbúra irọ́ ẹnu yín) ti di ohun mímọ̀ (fún wa).” Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[54] Sọ pé: "Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́ náà. Tí wọ́n bá pẹ̀yìn dà, ohun tí A gbé kà á lọ́rùn l’ó ń bẹ lọ́rùn rẹ̀, ohun tí A sì gbé kà yín lọ́rùn l’ó ń bẹ lọ́rùn yín. Tí ẹ bá sì tẹ̀lé e, ẹ máa mọ̀nà tààrà. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé

[55] Allāhu ṣàdéhùn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere pé dájúdájú Ó máa fi wọ́n ṣe àrólé lórí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe àrólé. Dájúdájú Ó máa fi àyè gba ẹ̀sìn wọn fún wọn, èyí tí Ó yọ́nú sí fún wọn. Lẹ́yìn ìbẹ̀rù wọn, dájúdájú Ó máa fi ìfàyàbalẹ̀ dípò rẹ̀ fún wọn. Wọ́n ń jọ́sìn fún Mi, wọn kò sì fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí Mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́

[56] Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà nítorí kí A lè kẹ yín

[57] Má ṣe lérò pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ mórí bọ́ nínú ìyà lórí ilẹ̀. Iná ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú

[58] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí àwọn ẹrú yín àti àwọn tí kò tí ì bàlágà nínú yín máa gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ yín nígbà mẹ́ta (wọ̀nyí): ṣíwájú ìrun Subh, nígbà tí ẹ bá ń bọ́ aṣọ yín sílẹ̀ fún òòrùn ọ̀sán àti lẹ́yìn ìrun alẹ́. (Ìgbà) mẹ́ta fún ìbọ́rasílẹ̀ yín (nìyí). Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin àti àwọn lẹ́yìn (àsìkò) náà pé kí wọ́n wọlé tọ̀ yín; kí apá kan yín wọlé tọ apá kan. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah náà fun yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[59] Nígbà tí àwọn ọmọdé yín bá sì bàlágà, kí àwọn náà máa gba ìyọ̀ǹda gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe gba ìyọ̀ǹda. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[60] Àwọn t’ó ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí nínú àwọn obìnrin, àwọn tí kò retí ìbálòpò oorun ìfẹ́ mọ́, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn láti bọ́ àwọn aṣọ jilbāb wọn sílẹ̀, tí wọn kò sì níí ṣe àfihàn ọ̀ṣọ́ kan síta. Kí wọ́n sì máa wọ aṣọ jilbāb wọn lọ bẹ́ẹ̀ lóore jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[61] Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà láti jẹun nínú ilé yín, tàbí ilé àwọn bàbá yín, tàbí ilé àwọn ìyá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin bàbá yín, tàbí ilé àwọn arákùnrin ìyá yín, tàbí ilé àwọn arábìnrin ìyá yín, tàbí (ilé) tí ẹ ní ìkápá lórí kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, tàbí (ilé) ọ̀rẹ́ yín. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín láti jẹun papọ̀ tàbí ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, tí ẹ bá wọ àwọn inú ilé kan, ẹ sálámọ̀ síra yín. (Èyí jẹ́) ìkíni ìbùkún t’ó dára láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fun yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè

[62] Àwọn onígbàgbọ́ ni àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá sì wà pẹ̀lú rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan tí ó kan gbogbogbò, wọn kò níí lọ títí wọn yóò fi gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú àwọn t’ó ń gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ fún apá kan ọ̀rọ̀ ara wọn, fún ẹni tí o bá fẹ́ ní ìyọ̀ǹda nínú wọn, kí o sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[63] Ẹ má ṣe ládìsọ́kàn pé ìpè Òjíṣẹ́ láààrin yín dà bí ìpè apá kan fún apá kan. Allāhu kúkú ti mọ àwọn t’ó ń yọ́ sá lọ nínú yín. Nítorí náà, kí àwọn t’ó ń yapa àṣẹ rẹ̀ ṣọ́ra nítorí kí ìdààmú má baà dé bá wọn, tàbí nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baá jẹ wọ́n

[64] Gbọ́! Dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì ti mọ ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí wọn yó dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

Òṣùwọ̀n

Surah 25

[1] Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá

[2] (Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n

[3] (Àwọn aláìgbàgbọ́) sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu. Wọn kò sì lè dá kiní kan. A sì dá wọn ni. Wọn kò sì ní ìkápá ìnira tàbí àǹfààní kan fún ẹ̀mí ara wọn. Àti pé wọn kò ní ìkápá lórí ikú, ìṣẹ̀mí àti àjíǹde

[4] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́ kan tí ó dá àdápa rẹ̀ (mọ́ Allāhu), tí àwọn ènìyàn mìíràn sì ràn án lọ́wọ́ lórí rẹ̀.” Dájúdájú (àwọn aláìgbàgbọ́) ti gbé àbòsí àti irọ́ dé

[5] Wọ́n tún wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́, tí ó ṣàdàkọ rẹ̀ ni. Òhun ni wọ́n ń pè fún un ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́.”

[6] Sọ pé: "Ẹni tí Ó mọ ìkọ̀kọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀. Dájúdájú Òun ni Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[7] Wọ́n tún wí pé: “Kí ló mú Òjíṣẹ́ yìí, t’ó ń jẹun, t’ó ń rìn nínú àwọn ọjà? Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ pẹ̀lú rẹ̀

[8] Tàbí (nítorí kí ni) wọn kò ṣe ju àpótí-ọrọ̀ kan sọ́dọ̀ rẹ̀, tàbí kí ó ní ọgbà oko kan tí ó ma máa jẹ nínú rẹ̀?” Àwọn alábòsí sì tún wí pé: “Ta ni ẹ̀ ń tẹ̀lé bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.”

[9] Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà

[10] Ìbùkún ni fún Ẹni tí (ó jẹ́ pé) bí Ó bá fẹ́, Ó máa ṣoore t’ó dára ju ìyẹn fún ọ. (Ó sì máa jẹ́) àwọn ọgbà tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ó sì máa fún ọ ni àwọn ààfin kan

[11] Ńṣe ni wọ́n pe Àkókò náà nírọ́. A sì ti pèsè Iná t’ó ń jò sílẹ̀ de ẹnikẹ́ni tí ó bá pe Àkókò náà nírọ́

[12] Nígbà tí (Iná náà) bá rí wọn láti àyè kan tí ó jìnnà, wọn yó sì máa gbọ́ ohùn ìbínú àti kíkùn (rẹ̀)

[13] Nígbà tí Wọ́n bá sì jù wọ́n sí àyè t’ó há gádígádí nínú (Iná), tí wọ́n de ọwọ́ wọn mọ́ wọn lọ́rùn, wọn yó sì máa kígbe ìparun níbẹ̀

[14] (A ó sọ pé): “Ẹ má ṣe kígbe ìparun ẹyọ kan, ẹ kígbe ìparun lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”

[15] Sọ pé: “Ǹjẹ́ ìyẹn ló lóore jùlọ ni tàbí Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, èyí tí A ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu. Ó sì jẹ́ ẹ̀san àti ìkángun rere fún wọn

[16] Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn nínú rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n (nínú rẹ̀). (Èyí) jẹ́ àdéhùn tí wọ́n ti tọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ

[17] Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó àwọn abọ̀rìṣà àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu jọ, (Allāhu) yó sì sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣi àwọn ẹrúsìn Mi wọ̀nyí lọ́nà ni tàbí àwọn ni wọ́n ṣìnà (fúnra wọn)?”

[18] Wọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Kò tọ́ fún wa láti mú àwọn kan ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Rẹ. Ṣùgbọ́n Ìwọ l’O fún àwọn àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn, títí wọ́n fi gbàgbé Ìrántí. Wọ́n sì jẹ́ ẹni ìparun.”

[19] (Allāhu sọ pé): “Dájúdájú àwọn òrìṣà ti pe ẹ̀yin abọ̀rìṣà ní òpùrọ́ nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n). Ní báyìí wọn kò lè gbé ìyà Iná kúrò fun yín, wọn kò sì lè ràn yín lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣe àbòsí (ẹbọ ṣíṣe) nínú yín, A sì máa fún un ní ìyà t’ó tóbi tọ́ wò.”

[20] A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ rí ṣíwájú rẹ àfi kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì rìn nínú ọjà. A ti fi apá kan yín ṣe àdánwò fún apá kan, ǹjẹ́ ẹ máa ṣe sùúrù bí? Olúwa Rẹ sì ń jẹ́ Olùríran

[21] Àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) wí pé: “Wọn kò ṣe sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wa, tàbí kí á rí Olúwa wa (sójú nílé ayé)? Dájúdájú wọ́n ti ṣègbéraga nínú ẹ̀mí wọn. Wọ́n sì ti tayọ ẹnu-ànà ní ìtayọ-ẹnu àlà t’ó tóbi

[22] (Rántí) ọjọ́ tí wọ́n yóò rí àwọn mọlāika, kò níí sí ìró ìdùnnú fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. (Àwọn mọlāika) yó sì sọ pé: “Èèwọ̀, èèwọ̀ (ni ìró ìdùnnú fún ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀).”

[23] Àti pé A máa wá ṣíbi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa sọ ọ́ di eruku àfẹ́dànù

[24] Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ní ọjọ́ yẹn, (ọgbà wọn) máa lóore jùlọ ní ibùgbé. Ó sì máa dára jùlọ ní ibùsinmi

[25] Àti pé (rántí) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó fàya pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣújò funfun. A sì máa sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ tààrà

[26] Ìjọba òdodo ti ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Àjọkẹ́-ayé. Ó sì jẹ́ ọjọ́ kan tí ó máa nira fún àwọn aláìgbàgbọ́

[27] (Rántí) ọjọ́ tí alábòsí yóò jẹ ìka ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ó sì máa wí pé: "Yéè! Èmi ìbá ti tọ ọ̀nà kan (náà) pẹ̀lú Òjíṣẹ́ náà

[28] Ègbé mi o, yéè! Èmi ìbá tí mú lágbájá ní ọ̀rẹ́ àyò

[29] Dájúdájú ó ti ṣì mí lọ́nà kúrò níbi Ìrántí lẹ́yìn tí ó dé bá mi. Dájúdájú Èṣù ń jẹ́ adáni-dáṣòro fún ọmọnìyàn

[30] Òjíṣẹ́ náà sọ pé: “Olúwa mi dájúdájú àwọn ènìyàn mi tí pa al-Ƙur’ān yìí tì.”

[31] Báyẹn ni A ṣe àwọn kan nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan. Olúwa rẹ sì tó ní Afinimọ̀nà àti Alárànṣe

[32] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Wọn kò ṣe sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún un ní àpapọ̀ ní ẹ̀ẹ̀ kan náà?” (A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀) báyẹn nítorí kí A lè fi rinlẹ̀ sínú ọkàn rẹ. A sì ké e fún ọ díẹ̀díẹ̀

[33] Wọn kò níí mú àpẹẹrẹ kan wá fún ọ (bí ìbéèrè láti fi takò ọ́) àfi kí Á mú òdodo (ìyẹn, al-ƙur’ān) àti àlàyé t’ó dára jùlọ wá fún ọ (lórí rẹ̀)

[34] Àwọn tí A máa kó jọ lọ sínú iná Jahanamọ ní ìdojúbolẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àyè wọn burú jùlọ. Wọ́n sì ṣìnà jùlọ

[35] Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A tún ṣe arákùnrin rẹ̀, Hārūn, ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún un

[36] A sì sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ sọ́dọ̀ ìjọ t’ó pe àwọn āyah Wa nírọ́. A sì pa ìjọ náà run pátápátá

[37] (Rántí) ìjọ (Ànábì) Nūh. Nígbà tí wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́, A tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì kan fún àwọn ènìyàn. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn alábòsí

[38] (Rántí) àwọn ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd, ìjọ Rass àti àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran mìíràn (t’ó ń bẹ) láààrin wọn

[39] Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fún ní àwọn àpèjúwe (nípa àwọn t’ó tako òdodo). Ìkọ̀ọ̀kan wọn sì ni A parun pátápátá

[40] Àti pé dájúdájú wọ́n kọjá ní ìlú tí A rọ òjò burúkú lé lórí. Ṣé wọn kì í rí i ni? Rárá, ńṣe ni wọn kò retí Àjíǹde

[41] Nígbà tí wọ́n bá sì rí ọ, kò sí ohun tí wọn yóò fi ọ́ ṣe bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. (Wọ́n á wí pé): “Ṣé èyí ni ẹni tí Allāhu gbé dìde ní Òjíṣẹ́

[42] Ó mà fẹ́ẹ̀ ṣẹ́rí wa kúrò níbi àwọn ọlọ́hun wa, tí kì í bá ṣe pé a takú sorí rẹ̀.” Láìpẹ́ wọn máa mọ ẹni tí ó ṣìnà jùlọ nígbà tí wọ́n bá rí ìyà

[43] Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀! Nítorí náà, ṣé ìwọ máa jẹ́ aláàbò fún un ni (níbi ìyà)

[44] Tàbí ìwọ ń rò pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ń gbọ́ràn tàbí pé wọ́n ń ṣe làákàyè? Kí ni wọ́n ná, bí kò ṣe bí àgùtàn. Wọ́n wulẹ̀ ṣìnà jùlọ

[45] Ṣé o ò rí (iṣẹ́) Olúwa rẹ ni, bí Ó ṣe fẹ òkùnkùn òwúrọ̀ lójú (sójú sánmọ̀)? Tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá dá a dúró síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, A fi òòrùn ṣe atọ́ka sí bíbẹ òkùnkùn

[46] Lẹ́yìn náà, A (fi ìmọ́lẹ̀ òòrùn) mú òkùnkùn (kúrò níta) wá sí ọ̀dọ̀ Wa ní mímú díẹ̀díẹ̀ (kí ojúmọ́ lè mọ́)

[47] Àti pé Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru ní ìbora fun yín. (Ó ṣe) oorun ní ìsinmi (fun yín). Ó tún ṣe ọ̀sán ní àsìkò ìtúsíta (fún wíwá ìjẹ-ìmu)

[48] Òun sì ni Ẹni t’’Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró-ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀. A sì sọ omi mímọ́ kalẹ̀ láti sánmọ̀

[49] nítorí kí A lè fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀ àti nítorí kí A lè fún ẹran-ọ̀sìn àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn nínú àwọn tí A dá ní omi mu

[50] Dájúdájú A ti pín omi yìí láààrin wọn nítorí kí wọ́n lè rántí (ìkẹ́ Olúwa wọn). Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ (láti rántí) àfi àìmoore

[51] Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, A ìbá gbé olùkìlọ̀ kan dìde nínú ìlú kọ̀ọ̀kan

[52] Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́. Kí o sì fi (al-Ƙur’ān) jà wọ́n ní ogun t’ó tóbi

[53] Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn odò méjì ṣàn kiri. Èyí (ni omi) t’ó dùn gan-an. Èyí sì (ni omi) iyọ̀ t’ó móró. Ó fi gàgá sí ààrin àwọn méjèèjì. (Ó sì) ṣe é ní èèwọ̀ pọ́nńbélé (fún wọn láti kó ìnira bá ẹ̀dá)

[54] Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá abara láti inú omi. Ó ṣe ìbátan ẹbí àti ìbátan àna fún un, Olúwa rẹ sì ń jẹ́ Alágbára

[55] Wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè ṣe wọ́n ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wọn. Aláìgbàgbọ́ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (fún Èṣù) láti tako Olúwa rẹ̀

[56] A kò sì rán ọ níṣẹ́ tayọ kí o jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀

[57] Sọ pé: “Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ àfi ẹni tí ó bá fẹ́ mú ọ̀nà (dáadáa) tọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.”

[58] Gbáralé Alààyè tí kò níí kú. Ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Un. Allāhu sì tó ní Alámọ̀tán nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀

[59] (Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan t’ó ń bẹ láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Àjọkẹ́-ayé ni, nítorí náà, bèèrè nípa Rẹ̀ (lọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí pé, Ó jẹ́) Alámọ̀tán

[60] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ fún Àjọkẹ́-ayé.” Wọ́n á wí pé: “Kí ni Àjọkẹ-ayé? Ṣé kí á forí kanlẹ̀ fún ohun tí ò ń pa wá láṣẹ rẹ̀ ni?” (Ìpèpè náà) sì mú wọn lékún ní sísá-sẹ́yìn

[61] Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ṣe àwọn ìràwọ̀ sínú sánmọ̀. Ó tún ṣe òòrùn àti òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú rẹ̀

[62] Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru àti ọ̀sán ní ìtẹ̀léǹtẹ̀lé (tí ìkíní yàtọ̀ sí ìkejì) nítorí ẹni tí ó bá gbèrò láti ṣe ìrántí (Allāhu) tàbí tí ó bá gbèrò ìdúpẹ́ (fún Un)

[63] Àwọn ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé ni àwọn t’ó ń rìn jẹ́ẹ́jẹ́ lórí ilẹ̀. Nígbà tí àwọn òpè bá sì dojú ọ̀rọ̀ kọ wọ́n, wọn yóò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà

[64] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń lo òru wọn ní ìforíkanlẹ̀ àti ìdúró-kírun fún Olúwa wọn

[65] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń sọ pé: “Olúwa wa, gbé ìyà iná Jahanamọ kúrò fún wa. Dájúdájú ìyà rẹ̀ jẹ́ ìyà àìnípẹ̀kun

[66] Dájúdájú ó burú ní ibùgbé àti ibùdúró

[67] Àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá náwó, wọn kò ná ìná-àpà, wọn kò sì ṣahun; (ìnáwó wọn) wà láààrin ìyẹn ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì

[68] (Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe (aburú) yẹn, ó máa pàdé (ìyà) ẹ̀ṣẹ̀

[69] A óò ṣe ìyà ní ìlọ́po fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ

[70] Àfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò fi iṣẹ́ rere rọ́pò iṣẹ́ aburú wọn (ìyẹn, nípa ìronúpìwàdà wọn). Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[71] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (kí ó mọ̀) pé dájúdájú ó ń ronú pìwàdà pátápátá sọ́dọ̀ Allāhu ni

[72] (Àwọn ni) àwọn tí kò jẹ́rìí èké. Tí wọ́n bá sì kọjá níbi ìbàjẹ́, wọ́n á kọjá pẹ̀lú àpọ́nlé

[73] (Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá fi àwọn āyah Olúwa wọn ṣèrántí fún wọn, wọn kò dà lulẹ̀ bí adití àti afọ́jú

[74] (Àwọn ni) àwọn t’ó ń sọ pé: “Olúwa wa, ta wá ní ọrẹ ìtutù-ojú láti ara àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa. Kí O sì ṣe wá ní aṣíwájú fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ).”

[75] Àwọn wọ̀nyẹn, ipò gíga (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni A máa fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù. Ìkíni àti sísálámọ̀ ni A óò fi máa pàdé wọn nínú rẹ̀

[76] Olúṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó dára ní ibùgbé àti ibùdúró

[77] Sọ pé: "Olúwa mi kò kà yín kún tí kì í bá ṣe àdúà yín. Ẹ kúkú ti pe (àwọn āyah Rẹ̀) nírọ́. Láìpẹ́ ó sì máa di ìyà àìnípẹ̀kun (fun yín)

Àwọn Akéwì

Surah 26

[1] Tọ̄ sīn mīm

[2] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá

[3] Nítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[4] Tí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un

[5] Kò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀

[6] Dájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn

[7] Ṣé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀

[8] Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[9] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[10] (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: "Lọ bá ìjọ alábòsí

[11] ìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé 'Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni

[12] Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́

[13] Ó sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn

[14] Àti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí

[15] (Allāhu) sọ pé: "Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín)

[16] Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: 'Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[17] (À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ

[18] (Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ

[19] O sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.”

[20] (Ànábì Mūsā) sọ pé: "Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláìmọ̀kan ni

[21] Mo sì sá fun yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Nítorí náà, Allāhu ti ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́

[22] Àti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́)

[23] Fir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”

[24] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni)

[25] (Fir‘aon) wí fún àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (t’ó ń sọ ni)?”

[26] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

[27] (Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.”

[28] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.”

[29] (Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.”

[30] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan t’ó yanjú wá fún ọ ńkọ́?”

[31] (Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”

[32] Nítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé

[33] Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran

[34] (Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa

[35] Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”

[36] Wọ́n wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú

[37] (pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ

[38] Wọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀

[39] Wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: "Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí

[40] Nítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí

[41] Nígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?”

[42] (Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”

[43] (Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”

[44] Wọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.”

[45] Nígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló

[46] Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu)

[47] Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[48] Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn

[49] Fir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”

[50] (Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa

[51] Dájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.”

[52] A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé) dájúdájú wọn yóò lépa yín.”

[53] Fir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé)

[54] Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n

[55] Àti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun t’ó ń bí wa nínú

[56] Dájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura

[57] Nítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi

[58] àti àwọn àpótí-ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé

[59] Báyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl

[60] Wọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ

[61] Nígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.”

[62] (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.”

[63] A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà á). Ó sì pín (sí ọ̀nà méjìlá). Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá

[64] A sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn

[65] A gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá

[66] Lẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami)

[67] Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[68] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[69] Ka ìròyìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn

[70] Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”

[71] Wọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”

[72] (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n

[73] Tàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní oore tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?”

[74] Wọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa, tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni”

[75] (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún

[76] ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ìṣaájú

[77] Dájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[78] (Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí

[79] Ẹni t’Ó ń fún mi ní jíjẹ, t’Ó ń fún mi ní mímu

[80] Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn

[81] Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè

[82] Ẹni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san

[83] Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere

[84] Jẹ́ kí àwọn t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn (mi) máa sọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú dáadáa

[85] Ṣe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra

[86] Kí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà

[87] Má ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde

[88] Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní

[89] Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́

[90] A máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[91] Wọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà

[92] wọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?”

[93] (N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́

[94] Wọ́n sì máa taari gbogbo wọn sínú Iná; àwọn àti èṣù wọn

[95] àti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá

[96] (Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé

[97] A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[98] nígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[99] Kò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (èṣù) ẹlẹ́ṣẹ̀

[100] Kò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa

[101] Kò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa)

[102] Tí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[103] Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[104] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[105] Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́

[106] Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni

[107] Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín

[108] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[109] Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[110] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.”

[111] Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?”

[112] Ó sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi)

[113] Kò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura

[114] Èmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù

[115] Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”

[116] Wọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”

[117] Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́

[118] Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

[119] A la òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́

[120] Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn t’ó ṣẹ́kù rì sínú omi

[121] Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[122] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[123] Àwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́

[124] Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni

[125] Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín

[126] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[127] Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[128] Ṣé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀

[129] Ẹ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí)

[130] Nígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú

[131] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[132] Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀

[133] Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ

[134] àti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi

[135] Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fun yín.”

[136] Wọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o kìlọ̀ fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn olùkìlọ̀

[137] Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́

[138] Wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”

[139] Nítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[140] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[141] Àwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́

[142] Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni

[143] Dájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín

[144] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[145] Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[146] Ṣé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀

[147] nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi

[148] àti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí ọ̀gọ́mọ̀ rẹ̀ tutù

[149] Ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́

[150] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[151] Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn aláṣejù

[152] àwọn t’ó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.”

[153] Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì

[154] Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

[155] Ó sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀

[156] Ẹ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.”

[157] Wọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀

[158] Ìyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[159] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[160] Ìjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́

[161] Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni

[162] Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín

[163] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[164] Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[165] Ṣé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)

[166] Ẹ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fun yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.”

[167] Wọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.”

[168] Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùbínú sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín

[169] Olúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú)

[170] Nítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá

[171] Àfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́)

[172] Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run

[173] A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú

[174] Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[175] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[176] Àwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́

[177] Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni

[178] Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín

[179] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[180] Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[181] Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn olùdóṣùwọ̀nkù

[182] Ẹ fi ìwọ̀n t’ó tọ́ wọn n̄ǹkan

[183] Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe hùwà aburú lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́

[184] Kí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ìran àkọ́kọ́.”

[185] Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì

[186] Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a ò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé ó wà nínú àwọn òpùrọ́

[187] Nítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

[188] Ó sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[189] Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá

[190] Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[191] Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[192] Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[193] Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀

[194] sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀

[195] pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé

[196] Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) ti wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́

[197] Ṣé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)

[198] Tí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni

[199] tí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo

[200] Báyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

[201] Wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[202] (Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura

[203] Nígbà náà ni wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí

[204] Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú

[205] Sọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ

[206] Lẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn dé bá wọn

[207] Ohun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀

[208] A ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀

[209] Ìrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí

[210] Kì í ṣe àwọn èṣù ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀

[211] Kò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀

[212] Dájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀)

[213] Nítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà

[214] Kí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ, t’ó súnmọ́ jùlọ

[215] Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn t’ó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[216] Tí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).”

[217] Kí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[218] Ẹni t’Ó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)

[219] àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀

[220] Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[221] Ṣé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn èṣù ń sọ̀kalẹ̀ wá bá

[222] Wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀

[223] (Àwọn èṣù) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́

[224] Àwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn

[225] Ṣé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni

[226] Àti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe

[227] Àfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn t’ó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí

Kòkòrò

Surah 27

[1] Tọ̄ sīn. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah al-Ƙur’ān àti (àwọn āyah) Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá

[2] (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[3] àwọn t’ó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[4] Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti ṣe àwọn iṣẹ́ (aburú ọwọ́) wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, Nítorí náà, wọn yó sì máa pa rìdàrìdà

[5] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìyà burúkú wà fún. Àwọn sì ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[6] Dájúdájú ò ń gba al-Ƙur’ān làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

[7] (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo rí iná kan. Mo sì máa lọ mú ìró kan wá fun yín láti ibẹ̀, tàbí kí n̄g mú ògúnná kan t’ó ń tanná wá fun yín nítorí kí ẹ lè yẹ́ná

[8] Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pèpè pé kí ìbùkún máa bẹ fún ẹni tí ó wà níbi iná náà àti ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Mímọ́ sì ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[9] Mūsā, dájúdájú Èmi ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[10] Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀. (Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.) Àmọ́ nígbà tí ó rí i t’ó ń yíra padà bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìn dà, ó ń sá lọ. Kò sì padà. (Allāhu sọ pé:) Mūsā, má ṣe páyà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kì í páyà lọ́dọ̀ Mi

[11] Àyàfi ẹni tí ó bá ṣàbòsí, lẹ́yìn náà tí ó yí i padà sí rere lẹ́yìn aburú. Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[12] Ti ọwọ́ rẹ bọ (abíyá láti ibi) ọrùn ẹ̀wù rẹ. Ó sì máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe ti aburú. (Èyí wà) nínú àwọn àmì mẹ́sàn-án (tí o máa mú lọ) bá Fir‘aon àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[13] Nígbà tí àwọn àmì Wa, t’ó fojú hàn kedere, sì dé bá wọn, wọ́n wí pé: “Èyí ni idán pọ́nńbélé.”

[14] Wọ́n takò ó pẹ̀lú àbòsí àti ìgbéraga, ẹ̀mí wọn sì ní àmọ̀dájú pé òdodo ni. Nítorí náà, wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ti rí

[15] Dájúdájú A fún (Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n ní ìmọ̀. Àwọn méjèèjì sì sọ pé: "Ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ẹni tí Ó fún wa ní oore àjùlọ lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[16] (Ànábì) Sulaemọ̄n sì jogún (Ànábì) Dāwūd. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi ohùn ẹyẹ mọ̀ wá. Wọ́n sì fún wa ní gbogbo n̄ǹkan. Dájúdájú èyí, òhun ni oore àjùlọ pọ́nńbélé

[17] A sì kó jọ fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú àlùjànnú, ènìyàn àti ẹyẹ. A sì ń kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn

[18] títí wọ́n fi dé àfonífojì àwọn àwúrèbe. Àwúrèbe kan sì wí pé: "Ẹ̀yin àwúrèbe, ẹ wọ inú ilé yín lọ, kí (Ànábì) Sulaemọ̄n àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ má baà tẹ̀ yín rẹ́ mọ́lẹ̀. Wọn kò sì níí fura

[19] Nígbà náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) rẹ́rìn-ín músẹ́, ẹ̀rín pa á nítorí ọ̀rọ̀ (àwúrèbe náà). Ó sọ pé: “Olúwa mi, fi mọ̀ mí bí mo ṣe máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí O fi ṣe ìdẹ̀ra fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì. (Fi mọ̀ mí) bí mo ṣe máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Pẹ̀lú àánú Rẹ fi mí sáààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni rere.”

[20] Ó ṣàbẹ̀wò àwọn ẹyẹ, ó sì sọ pé: “Nítorí kí ni mi ò ṣe rí ẹyẹ hudhuda? Àbí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí kò wá ni

[21] Dájúdájú mo máa jẹ ẹ́ níyà líle, tàbí kí n̄g dúńbú rẹ̀, tàbí kí ó mú ẹ̀rí t’ó yanjú wá fún mi.”

[22] (Ànábì Sulaemọ̄n) kò dúró pẹ́ (títí ó fi dé), ó sì wí pé: "Mo mọ n̄ǹkan tí o ò mọ̀. Mo sì mú ìró kan t’ó dájú wá bá ọ láti ìlú Saba’i

[23] Dájúdájú èmi bá obìnrin kan (níbẹ̀), t’ó ń ṣe ìjọba lé wọn lórí. Wọ́n fún un ní gbogbo n̄ǹkan. Ó sì ní ìtẹ́ ńlá kan

[24] Mo sì bá òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún òòrùn lẹ́yìn Allāhu. Èṣù sì ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (òdodo). Nítorí náà, wọn kò sì mọ̀nà

[25] láti forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni t’Ó ń mú ọrọ̀ t’ó pamọ́ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ jáde, Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn

[26] Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ ńlá

[27] Ó sọ pé: "A máa wòye bóyá òdodo l’o sọ ni tàbí o wà nínú àwọn òpùrọ́

[28] Mú ìwé mi yìí lọ, kí o jù ú sí wọn. Lẹ́yìn náà, kí o takété sí wọn, kí o sì wo ohun tí wọn yóò dá padà (ní èsì)

[29] (Bilƙīs) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, dájúdájú wọ́n ti ju ìwé alápọ̀n-ọ́nlé kan sí mi

[30] Dájúdájú ó wá láti ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n. Dájúdájú ó (sọ pé) “Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[31] Kí ẹ má ṣègbéraga sí mi, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi (láti di) mùsùlùmí.”

[32] (Bilƙīs) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ gbà mí ní ìmọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì í gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan títí ẹ máa fi jẹ́rìí sí i.”

[33] Wọ́n wí pé: “Alágbára ni àwa. Akọni ogun sì tún ni wá. Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọ̀rọ̀ wà. Nítorí náà, wòye sí ohun tí o máa pa láṣẹ.”

[34] (Bilƙīs) wí pé: “Dájúdájú àwọn ọba, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ìlú kan, wọn yóò bà á jẹ́. Wọn yó sì sọ àwọn ẹni abiyì ibẹ̀ di ẹni yẹpẹrẹ. Báyẹn ni wọ́n máa ń ṣe

[35] Dájúdájú mo máa fi ẹ̀bùn kan ránṣẹ́ sí wọn. Mo sì máa wòye sí ohun tí àwọn ìránṣẹ́ yóò mú padà (ní èsì).”

[36] Nígbà tí (ìránṣẹ́) dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n, ó sọ pé: “Ṣé ẹ máa fi owó ràn mí lọ́wọ́ ni? Ohun tí Allāhu fún mi lóore jùlọ sí ohun tí ẹ fún mi. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin tún ń yọ̀ lórí ẹ̀bùn yín

[37] Padà sí ọ̀dọ̀ wọn. Dájúdájú à ń bọ̀ wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lè kojú rẹ̀. Dájúdájú a máa mú wọn jáde kúrò nínú (ìlú wọn) ní ẹni àbùkù. Wọn yó sì di ẹni yẹpẹrẹ.”

[38] (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èwo nínú yín l’ó máa gbé ìtẹ́ (Bilƙīs) wá bá mi, ṣíwájú kí wọ́n tó wá bá mi (láti di) mùsùlùmí.”

[39] ‘Ifrīt nínú àwọn àlùjànnú sọ pé: “Èmi yóò gbe wá fún ọ ṣíwájú kí o tó dìde kúrò ní àyè rẹ. Dájúdájú èmi ni alágbára, olùfọkàntán lórí rẹ̀.”

[40] Ẹni tí ìmọ̀ kan láti inú tírà wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Èmi yóò gbé e wá fún ọ ṣíwájú kí o tó ṣẹ́jú.” Nígbà tí ó rí i tí ó dé sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí wà nínú oore àjùlọ Olúwa mi, láti fi dán mi wò bóyá mo máa dúpẹ́ tàbí mo máa ṣàì moore. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́ (fún Allāhu), ó dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàìmoore, dájúdájú Olúwa mi ni Ọlọ́rọ̀, Alápọ̀n-ọ́nlé.”

[41] Ó sọ pé: “Ẹ ṣe ìyípadà ìrísí ìtẹ́ rẹ̀ fún un, kí á wò ó bóyá ó máa dá a mọ̀ tàbí ó máa wà nínú àwọn tí kò níí dá a mọ̀.”

[42] Nígbà tí (Bilƙīs) dé, wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé bí ìtẹ́ rẹ ṣe rí nìyí?” Ó wí pé: "Ó dà bí ẹni pé òhun ni." (Ànábì Sulaemọ̄n sì sọ pé): “Wọ́n ti fún wa ní ìmọ̀ ṣíwájú Bilƙīs. A sì jẹ́ mùsùlùmí.”

[43] Ohun t’ó ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu sì ṣẹ́rí rẹ̀ (kúrò níbi ìjọ́sìn fún Allāhu). Dájúdájú ó wà nínú ìjọ aláìgbàgbọ́

[44] Wọ́n sọ fún un pé: “Wọ inú ààfin.” Nígbà tí ó rí i, ó ṣe bí ibúdò ni. Ó sì ká aṣọ kúrò ní ojúgun rẹ̀ méjèèjì. (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: “Dájúdájú ààfin tí a ṣe rigidin pẹ̀lú díńgí ni.” (Bilƙīs) sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú mo ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Mo sì di mùsùlùmí pẹ̀lú (Ànábì) Sulaemọ̄n, fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[45] Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí ìjọ Thamūd. (A rán) arákùnrin wọn, Sọ̄lih (níṣẹ́ sí wọn), pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu." Nígbà náà ni wọ́n pín sí ìjọ méjì, t’ó ń bára wọn jiyàn

[46] Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá (ìyà) aburú pẹ̀lú ìkánjú ṣíwájú (ohun) rere (t’ó yẹ kí ẹ mú ṣe níṣẹ́)? Ẹ ò ṣe tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu nítorí kí Wọ́n lè ṣàánú yín?”

[47] Wọ́n wí pé: “A rí àmì aburú láti ọ̀dọ̀ rẹ àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ.” (Ànábì Sọ̄lih) sọ pé: “Àmì aburú yín wà (nínú kádàrá yín) lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sì rí bí ẹ ṣe rò ó àmọ́ ìjọ aládàn-ánwò ni yín ni.”

[48] Àwọn ènìyàn mẹ́sàn-án kan sì wà nínú ìlú, tí wọ́n ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere

[49] Wọ́n wí (fúnra wọn) pé: “Kí á dìjọ fí Allāhu búra pé dájúdájú a máa pa òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní òru. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa sọ fún ẹbí rẹ̀ pé ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣojú wa. Dájúdájú olódodo sì ni àwa.”

[50] Wọ́n déte gan-an, Àwa náà sì déte gan-an, wọn kò sì fura

[51] Wo bí àtubọ̀tán ète wọn ti rí. Dájúdájú A pa àwọn àti ìjọ wọn run pátápátá

[52] Nítorí náà, ìwọ̀nyẹn ni ilé wọn. Ó tí di ilé ahoro nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó nímọ̀

[53] A gba àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo là, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu)

[54] (A tún fi iṣẹ́ ìmísí rán Ànábì) Lūt. (Rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé iṣẹ́ aburú ni ẹ óò máa ṣe ni, ẹ sì ríran

[55] Ṣé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa lọ jẹ adùn (ìbálòpọ̀) lára àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín ni) dípò àwọn obìnrin? Àní sẹ́, òpè ènìyàn ni yín

[56] Kò sí ohun kan tí ìjọ rẹ̀ fọ̀ ní èsì tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ lé àwọn ènìyàn Lūt jáde kúrò nínú ìlú yín. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn t’ó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀).”

[57] Nítorí náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ ọ́ pé ó máa wà nínú àwọn t’ó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun

[58] A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú

[59] Sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Kí àlàáfíà máa bá àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn tí Ó ṣà lẹ́ṣà. Ṣé Allāhu l’Ó lóore jùlọ ni tàbí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀

[60] (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó lóore jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sọ omi kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀, tí A sì fi omi náà hu àwọn ọgbà oko tí ó dára jáde? Kò sì sí agbára fun yín láti mu igi rẹ̀ hù jáde. Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Rárá, ìjọ t’ó ń ṣẹbọ sí Allāhu ni wọ́n ni

[61] (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ibùgbé, tí Ó fi àwọn odò sáààrin rẹ̀, tí Ó fi àwọn àpáta t’ó dúró ṣinṣin sínú ilẹ̀, tí Ó sì fi gàgá sáààrin ibúdò méjèèjì? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[62] (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń jẹ́pè ẹni tí ara ń ni nígbà tí ó bá pè É, tí Ó sì máa gbé aburú kúrò fún un, tí Ó sì ń ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Díẹ̀ ni ohun tí ẹ̀ ń lò nínú ìrántí

[63] (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń tọ yín sọ́nà nínú àwọn òkùnkùn orí ilẹ̀ àti inú ibúdò, tí Ó tún ń fi atẹ́gùn ránṣẹ́ ní ìró ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Allāhu ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[64] (Ṣé ìbọ̀rìṣà l’ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí Ó máa dá a padà (lẹ́yìn ikú), tí Ó sì ń pèsè fun yín láti sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: "Ẹ mú ẹ̀rí yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[65] Sọ pé: “Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àfi Allāhu. Àti pé wọn kò sì mọ àsìkò wo ni A máa gbé àwọn òkú dìde.”

[66] Bẹ́ẹ̀ ni, ní ọ̀run ni ìmọ̀ wọn máa tó mọ Ọjọ́ Ìkẹ́yìn (lọ́ràn). Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ (báyìí). Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti fọ́nú-fọ́ra nípa rẹ̀

[67] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ṣé nígbà tí àwa àti àwọn bàbá wa bá ti di erùpẹ̀, ṣé (nígbà náà ni) wọn yóò mú wa jáde

[68] Wọ́n kúkú tí ṣe àdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

[69] Sọ pé: “Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe rí.”

[70] Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń dá ní ète kó ìnira bá ọ

[71] Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

[72] Sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé apá kan ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ti súnmọ́ yín tán.”

[73] Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Ọlọ́lá lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kì í dúpẹ́ (fún Un)

[74] Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó kúkú mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń gbé pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀

[75] Àti pé kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó hàn kedere

[76] Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí yóò máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí

[77] Àti pé dájúdájú ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[78] Dájúdájú Olúwa rẹ máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú ìdájọ́ Rẹ̀. Òun ni Alágbára, Onímọ̀

[79] Nítorí náà, gbáralé Allāhu. Dájúdájú ìwọ wà lórí òdodo pọ́nńbélé

[80] Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ

[81] Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́ nítorí pé àwọn ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu

[82] Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà bá kò lé wọn lórí, A máa mú ẹranko kan jáde fún wọn láti inú ilẹ̀, tí ó máa bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú àwọn ènìyàn kì í nímọ̀ àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.”

[83] Àti pé (rántí) ọjọ́ tí A óò kó ìjọ kan jọ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan nínú àwọn t’ó ń pe àwọn āyah Wa nírọ́. A ó sì kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn

[84] Títí (di) ìgbà tí wọ́n bá dé (tán), (Allāhu) yóò sọ pé: "Ṣé ẹ pe àwọn āyah Mi nírọ́, tí ẹ̀yin kò sì ní ìmọ̀ kan nípa rẹ̀ (tí ẹ lè fi já a nírọ́)? Tàbí kí ni ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ (nílé ayé)

[85] Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀

[86] Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’A dá òru nítorí kí wọ́n lè sinmi nínú rẹ̀, (A sì dá) ọ̀sán (nítorí kí wọ́n lè) ríran? Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo

[87] (Rántí) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo, gbogbo ẹni tí ó wà nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ yó sì jáyà àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Gbogbo ẹ̀dá l’ó sì máa yẹpẹrẹ wá bá Allāhu

[88] O sì máa rí àwọn àpáta, tí o lérò pé n̄ǹkan gbagidi t’ó dúró sojú kan náà ni, tí ó máa rin ìrìn ẹ̀ṣújò. (Ìyẹn jẹ́) iṣẹ́ Allāhu, Ẹni tí Ó ṣe gbogbo n̄ǹkan ní dáadáa. Dájúdájú Ó mọ ìkọ̀kọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[89] Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú iṣẹ́ rere wá, tirẹ̀ ni rere t’ó lóore jùlọ sí èyí t’ó mú wá. Àwọn sì ni olùfàyàbalẹ̀ nínú ìjáyà ọjọ́ yẹn

[90] Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú (iṣẹ́) aburú wá, A sì máa da ojú wọn bolẹ̀ nínú Iná. Ǹjẹ́ A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[91] Ohun tí wọ́n pa mí ní àṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Olúwa Ìlú yìí, Ẹni tí Ó ṣe é ní àyè ọ̀wọ̀. TiRẹ̀ sì ni gbogbo n̄ǹkan. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn mùsùlùmí

[92] Àti pé kí n̄g máa ké al-Ƙur’ān. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, sọ pé: “Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùkìlọ̀.”

[93] Sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu.” (Allāhu) yóò fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ẹ̀yin yó sì mọ̀ wọ́n. Olúwa rẹ kò sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

Àwọn Ìtàn

Surah 28

[1] Tọ̄ sīn mīm

[2] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá

[3] À ń ké nínú ìró (Ànábì) Mūsā àti Fir‘aon fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí ìjọ t’ó gbàgbọ́ lódodo

[4] Dájúdájú Fir‘aon ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Ó ṣe àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìjọ-ìjọ. Ó ń dá igun kan nínú wọn lágara; ó ń pa àwọn ọmọkùnrin wọn, ó sì ń dá àwọn obìnrin wọn sí. Dájúdájú ó wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́

[5] A sì fẹ́ ṣèdẹ̀ra fún àwọn tí wọ́n fojú tínrín lórí ilẹ̀, A (fẹ́) ṣe wọ́n ní aṣíwájú. A sì (fẹ́) kí wọ́n jogún (ilẹ̀)

[6] A (fẹ́) gbà wọ́n láàyè lórí ilẹ̀. Láti ara wọn, A sì (fẹ́) fi han Fir‘aon àti Hāmọ̄n pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì ohun tí wọ́n ń ṣọ́ra fún lára wọn

[7] A sì ránṣẹ́ sí ìyá (Ànábì) Mūsā pé: “Fún un ní ọmú mu. Tí o bá sì ń páyà lórí rẹ̀, jù ú sínú agbami odò. Má ṣe bẹ̀rù. Má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú Àwa máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. A ó sì ṣe é ní ara àwọn Òjíṣẹ́

[8] Nígbà náà, àwọn ènìyàn Fir‘aon rí i he nítorí kí ó lè jẹ́ ọ̀tá àti ìbànújẹ́ fún wọn. Dájúdájú Fir‘aon, Hāmọ̄n àti àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì, wọ́n jẹ́ aláṣìṣe

[9] Ìyàwó Fir‘aon wí pé: “Ìtutù-ojú ni (ọmọ yìí) fún èmi àti ìwọ. Ẹ má ṣe pa á. Ó lè jẹ́ pé ó máa ṣe wá ní àǹfààní tàbí kí a fi ṣe ọmọ.” Wọn kò sì fura

[10] Ọkàn ìyá (Ànábì) Mūsā pami (lórí ọ̀rọ̀ Mūsā, kò sì rí n̄ǹkan mìíràn rò mọ́ tayọ rẹ̀) ó kúkú fẹ́ẹ̀ ṣàfi hàn rẹ̀ (pé ọmọ òun ni nígbà tí wọ́n pè é dé ọ̀dọ̀ Fir‘aon) tí kò bá jẹ́ pé A kì í lọ́kàn nítorí kí ó lè wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[11] Ó sì sọ fún arábìnrin rẹ̀ pé: “Tọpa rẹ̀ lọ.” Ó sì ń wò ó láti ibi t’ó jìnnà. Wọn kò sì fura (sí i)

[12] A kò sì jẹ́ kí ó mu ọyàn (mìíràn) ṣíwájú (tìyá rẹ̀.) Arábìnrin rẹ̀ sì wí pé: “Ṣé kí n̄g fi ará ilé kan hàn yín, tí ó máa gbà á tọ́ fun yín? Wọn yó sì jẹ́ olùtọ́jú rẹ̀.”

[13] A sì dá a padà sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ nítorí kí ojú rẹ̀ lè tutù (fún ìdùnnú) àti nítorí kí ó má baà banújẹ́. Àti pé nítorí kí ó lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu, òdodo ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[14] Nígbà t’ó dàgbà, t’ó di géńdé, A fún un ní ọgbọ́n àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san

[15] Ó wọ inú ìlú nígbà tí àwọn ará ìlú ti gbàgbé (nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀). Ó rí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n ń jà. Èyí wá láti inú ìran rẹ̀. Èyí sì wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Èyí tí ó wá láti inú ìran rẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Mūsā kàn án ní ẹ̀ṣẹ́. Ó sì pa á. Ó sọ pé: “Èyí wà nínú iṣẹ́ Èṣù. Dájúdájú (èṣù) ni ọ̀tá aṣini-lọ́nà pọ́nńbélé.”

[16] Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Nítorí náà, foríjìn mí.” Ó sì foríjìn ín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[17] Ó sọ pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe ìkẹ́ fún mi, èmi kò níí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

[18] Nítorí náà, ó di ẹni t’ó ń bẹ̀rù nínú ìlú, ó sì ń retí (ẹ̀hónú ìran Fir‘aon). Nígbà náà ni ẹni tí ó wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní àná tún ń lọgun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Mūsā sọ fún un pé: “Dájúdájú ìwọ ni olùṣìnà pọ́nńbélé.”

[19] Àmọ́ nígbà tí ó fẹ́ gbá ẹni tí ó jẹ́ ọ̀tá fún àwọn méjèèjì mú, ẹni náà wí pé: “Mūsā, ṣé o fẹ́ pa mí bí ó ṣe pa ẹnì kan ní àná? O ò gbèrò kan tayọ kí o jẹ́ aláìlójú-àánú lórí ilẹ̀; o ò sì gbèrò láti wà nínú àwọn alátùn-únṣe.”

[20] Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Mūsā, dájúdájú àwọn ìjòyè ń dá ìmọ̀ràn lórí rẹ láti pa ọ́. Nítorí náà, jáde (kúrò nínú ìlú), dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn rere fún ọ.”

[21] Ó sì jáde kúrò nínú (ìlú) pẹ̀lú ìpáyà, tí ó ń retí (ẹ̀hónú wọn), ó sì sọ pé: “Olúwa mi, là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”

[22] Nígbà tí ó sì dojú kọ ọ̀kánkán ìlú Mọdyan, ó sọ pé: “Ó súnmọ́ kí Olúwa mi fọ̀nà tààrà (sí ìlú Mọdyan) mọ̀ mí.”

[23] Nígbà tí ó dé ibi (kànǹga) omi (ìlú) Mọdyan, ó bá ìjọ ènìyàn kan níbẹ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn ní omi mu. Lẹ́yìn wọn, ó tún rí àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n ń fà sẹ́yìn (pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn wọn). Ó sọ pé: “Kí l’ó ṣe ẹ̀yin méjèèjì?” Wọ́n sọ pé: “A ò lè fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wa ní omi mu títí àwọn adaran bá tó kó àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn lọ. Àgbàlagbà arúgbó sì ni bàbá wa.”

[24] Ó sì bá wọn fún (ẹran-ọ̀sìn) wọn ní omi mu. Lẹ́yìn náà, ó padà síbi ibòji, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi bùkátà sí ohun tí O bá sọ̀kalẹ̀ fún mi nínú oore.”

[25] Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì wá bá a, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìtìjú, ó sọ pé: “Dájúdájú bàbá mi ń pè ọ́ nítorí kí ó lè san ọ́ ní ẹ̀san omi tí o fún (àwọn ẹran-ọ̀sìn) wa mu.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ ìtàn (ara rẹ̀) fún un. (Bàbá náà) sọ pé: “Má bẹ̀rù. O ti là lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”

[26] Ọ̀kan nínú (àwọn ọmọbìnrin) méjèèjì sọ pé: “Bàbá mi o, gbà á síṣẹ́. Dájúdájú ẹni t’ó dára jùlọ tí o lè gbà síṣẹ́ ni alágbára, olùfọkàntán.”

[27] Ó sọ pé: “Dájúdájú mo fẹ́ fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì wọ̀nyí fún ọ ní aya lórí (àdéhùn) pé o máa bá mi ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n tí o bá ṣe é pé ọdún mẹ́wàá, láti ọ̀dọ̀ rẹ nìyẹn. Èmi kò sì fẹ́ kó ìnira bá ọ. Tí Allāhu bá fẹ́, o máa rí i pé mo wà nínú àwọn ẹni rere.”

[28] (Mūsā) sọ pé: “(Àdéhùn) yìí wà láààrin èmi àti ìwọ. Èyíkéyìí tí mo bá mú ṣẹ nínú àdéhùn méjèèjì náà, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣàbòsí sí mi. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”

[29] Nígbà tí Mūsā parí àkókò náà, ó mú ará ilé rẹ̀ rin (ìrìn-àjò). Ó sì rí iná kan ní ẹ̀bá àpáta. Ó sọ fún ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró (síbí ná). Èmi rí iná kan. Ó ṣe é ṣe kí n̄g mú ìró kan wá ba yín láti ibẹ̀ tàbí (kí n̄g mú) ògúnná kan wá nítorí kí ẹ lè rí ohun yẹ́ná.”

[30] Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é láti ẹ̀gbẹ́ àfonífojì ní ọwọ́ ọ̀tún (rẹ̀) ní àyè ìbùkún láti ibi igi náà. (A sọ pé): “Mūsā, dájúdájú Èmi ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[31] Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” (Ó sì jù ú sílẹ̀). Nígbà tí ó rí i t’ó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìn dà, ó ń sá lọ́, kò sì padà. (Allāhu sọ pé): “Mūsā, máa bọ̀ padà, má sì ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn olùfàyàbalẹ̀

[32] Ti ọwọ́ rẹ bọ (abíyá láti ibi) ọrùn ẹ̀wù rẹ, ó sì máa jáde ní funfun tí kì í ṣe ti aburú. Pa ọwọ́ rẹ mọ́ra sí (abíyá rẹ) níbi ẹ̀rù. Nítorí náà, àwọn ẹ̀rí méjì nìwọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”

[33] (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pa ẹnì kan nínú wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí

[34] Àti pé arákùnrin mi, Hārūn, ó dá láhọ́n jù mí lọ. Nítorí náà, rán an níṣẹ́ pẹ̀lú mi, kí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí yóò máa jẹ́rìí sí òdodo ọ̀rọ̀ mi. Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.”

[35] (Allāhu) sọ pé: “A máa fi arákùnrin rẹ kún ọ lọ́wọ́. A ó sì fún ẹ̀yin méjèèjì ní agbára, wọn kò sì níí lè dé ọ̀dọ̀ ẹ̀yin méjèèjì. Pẹ̀lú àwọn àmì Wa, ẹ̀yin méjèèjì àti àwọn t’ó bá tẹ̀lé ẹ̀yin méjèèjì l’ó máa borí.”

[36] Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé bá wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àdáhun. A kò sì gbọ́ èyí (rí) láààrin àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

[37] (Ànábì) Mūsā sì sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti ẹni tí àtubọ̀tán ilé (ìkẹ́) máa jẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”

[38] Fir‘aon wí pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi! Nítorí náà, Hāmọ̄n, dá iná fún mi, kí o fi mọ amọ̀, kí o sì kọ́ ilé gíga kan fún mi nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā. (Nítorí pé) dájúdájú mò ń rò ó sí ara àwọn òpùrọ́.”

[39] Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì rò pé dájúdájú A ò níí dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Wa

[40] Nítorí náà, A gbá òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mú; A jù wọ́n sínú agbami odò. Wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ti rí

[41] A ṣe wọ́n ní aṣíwájú t’ó ń pèpè sínú Iná. Tí ó bá sì di Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́

[42] Àti pé A fi ègún tọpa wọn ní ilé ayé yìí. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yó sì wà nínú àwọn ẹni ìparun

[43] Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà lẹ́yìn ìgbà tí A ti pa àwọn ìjọ àkọ́kọ́ rẹ́. (Tírà náà jẹ́) àríwòye fún àwọn ènìyàn, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[44] Ìwọ kò sí ní ẹ̀bá ìwọ̀-òòrùn nígbà tí A fi ọ̀rọ̀ náà ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā. Àti pé ìwọ kò sí nínú àwọn t’ó wà níbẹ̀

[45] Ṣùgbọ́n A ṣẹ̀dá àwọn ìran kan tí ẹ̀mí wọn gùn. O ò kúkú gbé láààrin ará ìlú Mọdyan, tí ò ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, ṣùgbọ́n Àwa l’à ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́

[46] (Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí. 16:36 àti sūrah Fātir 35:24) bẹ́ẹ̀ náà l’a rí àwọn āyah mìíràn t’ó ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan rí sí àwọn Lárúbáwá (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọs kò sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu gbé dìde láààrin wọn sí gbogbo ìran wọn ní àpapọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Lárúbáwá ní àǹfààní láti gbọ́ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti ọmọ rẹ̀ Ànábì ’Ismọ̄‘īl pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn kan àmọ́ kò sí òye àtinúwá fún ìmọ̀ nípa bí wọ́n máa ṣe jọ́sìn fún Allāhu Ẹlẹ́dàá wọn àfi kí wọ́n ní Òjíṣẹ́ kan t’ó máa jẹ́ aṣíwájú fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni rere. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dìde ní àrà ọ̀tọ̀. Ìtúmọ̀ “ní àrà ọ̀tọ̀” ni pé

[47] Tí ó bá jẹ́ pé àdánwò kan kàn wọ́n nítorí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn tì síwájú, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa, ti Ó bá jẹ́ pé O rán Òjíṣẹ́ kan sí wa ni, a à bá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ, a à bá sì wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

[48] Ṣùgbọ́n nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní irú ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā?" Ṣé wọn kò sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí A fún (Ànábì) Mūsā ṣíwájú bí? Wọ́n wí pé: “Òpìdán méjì t’ó ń ranra wọn lọ́wọ́ (ni wọ́n).” Wọ́n sì tún wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìkọ̀ọ̀kan (wọn).”

[49] Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú tírà kan wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, t’ó ń tọ́ ni sí ọ̀nà ju ti àwọn méjèèjì lọ, mo sì máa tẹ̀lé e, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

[50] Tí wọn kò bá jẹ́pè rẹ, mọ̀ pé wọ́n kàn ń tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni. Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni t’ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, láì sí ìmọ̀nà (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu! Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[51] Àti pé dájúdájú A ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[52] Àwọn tí A fún ní Tírà ṣíwájú rẹ̀, wọ́n gba al-Ƙur’ān gbọ́

[53] Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọ́n á sọ pé: “A gbà á gbọ́. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa. Dájúdájú àwa ti jẹ́ mùsùlùmí ṣíwájú rẹ̀.”

[54] Àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní ẹ̀ẹ̀ mejì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù, wọ́n sì ń fi dáadáa ti àìdaa dànù. Àti pé wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn

[55] Àti pé nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ burúkú, wọ́n á ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀, wọ́n á sì sọ pé: “Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kí àlàáfíà máa ba yín. A kò wá àwọn aláìmọ̀kan (ní alábàáṣepọ̀).”

[56] Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà

[57] Wọ́n wí pé: “Tí a bá (fi lè) tẹ̀lé ìmọ̀nà pẹ̀lú rẹ, àwọn ọ̀ṣẹbọ yóò kó wa kúrò lórí ilẹ̀ wa.” Ṣé A ò fún wọn ní ibùgbé (tí ó jẹ́) àyè ọ̀wọ̀ ìfọ̀kànbalẹ̀, tí wọ́n sì ń kó àwọn èso gbogbo ìlú wá síbẹ̀, tí ó jẹ́ èsè láti ọ̀dọ̀ Wa? Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[58] Mélòó mélòó nínú ìlú tí A parẹ́, tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ ayé-jíjẹ nínú ìlú. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ibùgbé wọn, tí A kò jẹ́ kí ẹnì kan kan gbé ibẹ̀ lẹ́yìn wọn bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀. Àwa sì jẹ́ Olùjogún

[59] Olúwa rẹ kò sì níí pa àwọn ìlú run (ní àsìkò tìrẹ yìí) títí Ó fi máa gbé Òjíṣẹ́ kan dìde nínú Olú-ìlú-ayé (ìyẹn, ìlú Mọkkah, ẹni tí) yóò máa ké àwọn āyah Wa fún wọn. (Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.) A ò sì níí pa àwọn ìlú (yìí) run sẹ́ àfi kí àwọn ara ibẹ̀ jẹ́ alábòsí

[60] Kò sí ohun tí A fun yín bí kò ṣe nítorí ìgbádùn ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni

[61] Ǹjẹ́ ẹni tí A bá ṣàdéhùn ní àdéhùn t’ó dára, tí ó sì máa pàdé rẹ̀, dà bí ẹni tí A fún ní ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé bí, lẹ́yìn náà ní Ọjọ́ Àjíǹde tí ó máa wà nínú àwọn tí wọn yóò mú wá (fún ìyà Iná)

[62] (Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”

[63] Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí tí a kó ṣìnà, a kó wọn ṣìnà gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe ṣìnà. A yọwọ́ yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀ wọn) níwájú Rẹ (báyìí); kì í ṣe àwa ni wọ́n ń jọ́sìn fún.”

[64] A sọ (fún wọn) pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín.” Wọ́n sì pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dá wọn lóhùn. Wọ́n ti rí Iná. Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n jẹ́ olùmọ̀nà ni (ìyà ìbá tí jẹ wọ́n)

[65] (Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni ẹ fọ̀ ní èsì fún àwọn Òjíṣẹ́?”

[66] Èsì ọ̀rọ̀ yó sì fọ́jú pọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ọjọ́ yẹn; wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè

[67] Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ó súnmọ́ pé ó máa wà nínú àwọn olùjèrè

[68] Olúwa rẹ l’Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣa (ohun tí Ó bá fẹ́) ní ẹ̀ṣà. Ṣíṣa ẹ̀ṣà kò tọ́ sí wọn. Mímọ́ ni fún Allāhu. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[69] Olúwa rẹ sì mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀

[70] Òun sì ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. TiRẹ̀ ni ọpẹ́ ní ilé ayé yìí àti ní ọ̀run. TiRẹ̀ sì ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí

[71] Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ òru di ohun tí ó máa wà títí láéláé fun yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fun yín ní ìmọ́lẹ̀? Ṣé ẹ ò gbọ́rọ̀ ni?”

[72] Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ ọ̀sán di ohun tí ó máa wà títí láéláé fun yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fun yín ní alẹ́ tí ẹ óò máa sinmi nínú rẹ̀? Ṣé ẹ ò ríran ni?”

[73] Nínú ìkẹ́ Rẹ̀ (ni pé) Ó ṣe òru àti ọ̀sán fun yín; nítorí kí ẹ lè sinmi nínú (òru) àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀ (ní ọ̀sán) àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́

[74] (Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”

[75] A sì máa mú ẹlẹ́rìí kan jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. A máa sọ pé: “Ẹ mú ìdí ọ̀rọ̀ yín wá.” Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ń jẹ́ ti Allāhu. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ yó sì dòfo mọ́ wọn lọ́wọ́

[76] Dájúdájú Ƙọ̄rūn wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ṣùgbọ́n ó ṣègbéraga sí wọn. A sì fún un ní àwọn àpótí-ọrọ̀ èyí tí àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ wúwo láti gbé fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn alágbára. (Rántí) nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ fún un pé: "Má ṣe yọ ayọ̀ àyọ̀jù. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn aláyọ̀jù

[77] Fi n̄ǹkan tí Allāhu fún ọ wá ilé Ìkẹ́yìn. Má ṣe gbàgbé ìpín rẹ ní ilé ayé. Ṣe dáadáa gẹ́gẹ́ bí Allāhu ti ṣe dáadáa fún ọ. Má sì ṣe wá ìbàjẹ́ ṣe lórí ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn òbìlẹ̀jẹ́

[78] Ó wí pé: "Dájúdájú wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ mi ni." Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ti parun nínú àwọn ìran t’ó ṣíwájú rẹ̀, ẹni tí ó lágbára jù ú lọ, tí ó sì ní àkójọ ọrọ̀ jù ú lọ? A ò sì níí bi àwọn arúfin léèrè (ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó kúkú ti wà ní àkọsílẹ̀)

[79] Ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Àwọn t’ó ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí sì wí pé: “Háà! Kí á sì ní irú ohun tí wọ́n fún Ƙọ̄rūn. Dájúdájú ó ní ìpín ńlá nínú oore.”

[80] Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ sọ pé: “Ègbé ni fun yín! Ẹ̀san Allāhu lóore jùlọ fún ẹni t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì sí ẹni tí ó máa rí (ẹ̀san náà) gbà àfi àwọn onísùúrù.”

[81] Nítorí náà, A jẹ́ kí ilẹ̀ gbé òun àti ilé rẹ̀ mì. Kò ní ìjọ kan tí ó lè ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì sí nínú àwọn t’ó lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́

[82] Àwọn t’ó ń rankàn ipò rẹ̀ ní àná sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ṣé ẹ rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu kẹ́ wa ni, ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ gbé àwa náà mì ni. Ṣé ẹ rí i pé àwọn aláìmoore kò níí jèrè.”

[83] Ilé Ìkẹ́yìn yẹn, A máa fi fún àwọn tí kò fẹ́ máa ṣe ìgbéraga àti ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[84] Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú iṣẹ́ rere wá, tirẹ̀ ni rere t’ó lóore jùlọ sí èyí t’ó mú wá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú iṣẹ́ aburú wá, A ò sì níí san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san kan àfi ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[85] Dájúdájú Ẹni tí Ó ṣe al-Ƙur’ān ní ọ̀ran-anyàn fún ọ, Ó sì máa dá ọ padà sí èbúté kan. Sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá àti ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

[86] Ìwọ kò sì retí pé A óò sọ tírà al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ (tẹ́lẹ̀), àmọ́ ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ jẹ́ alátìlẹ́yìn fún àwọn aláìgbàgbọ́

[87] Má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́ ọ lórí kúrò níbi àwọn āyah Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí A ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ. Pèpè sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ

[88] Má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Gbogbo n̄ǹkan l’ó máa parun àfi Ojú Rẹ̀ (àfi Òun). TiRẹ̀ ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí

Alángbá

Surah 29

[1] ’Alif lām mīm

[2] Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lérò pé A óò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ pé: “A gbàgbọ́”, tí A ò sì níí dán wọn wò

[3] A kúkú ti dán àwọn t’ó ṣíwájú wọn wò. Nítorí náà, dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn t’ó sọ òdodo. Dájúdájú Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn òpùrọ́

[4] Àbí àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé àwọn máa mórí bọ́ mọ́ Wa lọ́wọ́ ni? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú

[5] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Allāhu, dájúdájú àkókò Allāhu kúkú ń bọ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[6] Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìyànjú, ó ń gbìyànjú fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá

[7] Àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa ha àwọn iṣẹ́ aburú wọn dànù fún wọn. Dájúdájú A ó sì san wọ́n lẹ́san pẹ̀lú èyí t’ó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe

[8] A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn láti ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[9] Àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọ́n sínú àwọn ẹni rere

[10] Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń wí pé: “A gba Allāhu gbọ́.” Nígbà tí wọ́n bá sì fi ìnira kàn wọ́n nínú ẹ̀sìn Allāhu, ó máa sọ ìnira ènìyàn dà bí ìyà ti Allāhu. Tí àrànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ bá sì dé, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Dájúdájú àwa wà pẹ̀lú yín.” Ṣé Allāhu kọ́ l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà gbogbo ẹ̀dá ni

[11] Dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí

[12] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Ẹ tẹ̀lé ojú ọ̀nà tiwa nítorí kí á lè ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Wọn kò sì lè ru kiní kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n

[13] Dájúdájú wọn yóò ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn àti àwọn ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ kan mọ́ ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn. Àti pé dájúdájú A óò bi wọ́n léèrè ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́

[14] Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó gbé láààrin wọn fún ẹgbẹ̀rún ọdún àfi àádọ́ta ọdún. Ẹ̀kún-omi sì gbá wọn mú nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí

[15] A sì la òun àti àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá

[16] (Rántí Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì páyà Rẹ̀. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.”

[17] Ẹ kàn ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Ẹ sì ń dá àdápa irọ́. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, wọn kò ní ìkápá arísìkí kan fun yín. Ẹ wá arísìkí sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Kí ẹ jọ́sìn fún Un. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí

[18] Tí ẹ bá sì pe (òdodo) nírọ́, àwọn ìjọ kan t’ó ṣíwájú yín kúkú ti pe (òdodo) nírọ́. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé

[19] Tàbí wọn kò rí bí Allāhu ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá ni? Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu

[20] Sọ pé: “Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí Ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá (ní ìpìlẹ̀). Lẹ́yìn náà, Allāhu l’Ó máa mú ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn wá (fún àjíǹde). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”

[21] Ó ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì ń kẹ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí. ó jẹ́ ohun tí Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀dá náà nínú kádàrá rẹ̀ nítorí pé tibi-tire ni kádàrá ẹ̀dá. Fífẹ́bẹ́ẹ̀ yìí ni à ń pè ní ""mọṣī’atu-llāhi al-kaoniyyah"" “fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu tayé”. Bí àpẹẹrẹ lágbájá fẹ́ di olówó lọ́nà ẹ̀tọ́ ó jẹ́ ohun tí Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀dá nínú òfin àti ìlànà Rẹ̀. Allāhu kò sì níí fẹ́ òfin àti ìlànà kan bẹ́ẹ̀ nínú Tírà Rẹ̀ t’ó sọ̀kalẹ̀ fún wa àfi kí ó jẹ́ rere pọ́nńbélé tàbí kí rere rẹ̀ tẹ̀wọ̀n ju aburú rẹ̀ lọ. Fífẹ́bẹ́ẹ̀ yìí ni à ń pè ní ""mọṣī’atu-llāhi aṣ-ṣẹr‘iyyah"" “fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu tòfin”. Bí àpẹẹrẹ lágbájá fẹ́ di mùsùlùmí méjèèjì l’ó dúró sórí “ ‘adl” àti “ fọdl” – déédé àti ọlá. Àlàyé èyí ni pé tí ìyà bá jẹ́ lágbájá nílé ayé tàbí ní ọ̀run láì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo ẹnu ẹni kẹ́ni kò gbà á láti fi ẹ̀sùn kan Allāhu lórí fífẹ́bẹ́ẹ̀ Rẹ̀ lórí ẹ̀dá rẹ̀. Ṣebí nílé ayé yìí gan-an

[22] Àti pé ẹ̀yin kò níí mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu

[23] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu àti ìpàdé Rẹ̀ (lọ́run), àwọn wọ̀nyẹn ti sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Mi. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún

[24] Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ pa á tàbí kí ẹ sun ún níná.” Allāhu sì là á nínú iná. Dájúdájú àwọn àmì kúkú wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó gbàgbọ́ lódodo

[25] Ó sì sọ pé: “Ẹ kàn mú àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu, ní ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí (láti jọ́sìn fún) láààrin ara yín nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde apá kan yin yóò tako apá kan. Apá kan yín yó sì ṣẹ́bi lé apá kan. Iná sì ni ibùgbé yín. Kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan fun yín.”

[26] (Ànábì) Lūt sì gbà á gbọ́. (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Dájúdájú èmi yóò fi ìlú yìí sílẹ̀ nítorí ti Olúwa mi. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[27] A fi ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀) ta á lọ́rẹ. A sì ṣe jíjẹ́ Ànábì àti fífúnni ní tírà sínú àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀. A fún un ní ẹ̀san rẹ̀ ní ayé yìí. Dájúdájú ní ọ̀run, ó tún wà nínú àwọn ẹni rere

[28] (Rántí Ànábì) Lūt. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ń ṣe ìbàjẹ́ tí kò sí ẹnì kan nínú ẹ̀dá tí ó ṣe é rí ṣíwájú yín

[29] Ṣé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa tọ àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín) lọ (fún adùn ìbálòpọ̀), ẹ tún ń dánà, ẹ tún ń ṣe ohun burúkú nínú àkójọ yín? Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan àfi kí wọ́n wí pé : “Mú ìyà Allāhu wá fún wa tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”

[30] Ó sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mí lórí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”

[31] Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì mú ìró ìdùnnú dé bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, wọ́n sọ pé: “Dájúdájú àwa máa pa àwọn ará ìlú yìí run. Dájúdájú àwọn ará ìlú náà jẹ́ alábòsí.”

[32] Ó sọ pé: “Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà níbẹ̀! Wọ́n sọ pé: “Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn t’ó wà níbẹ̀. Dájúdájú àwa yóò la òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ àfi ìyàwó rẹ̀ tí ó máa wà nínú àwọn t’ó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.”

[33] Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Wọ́n sì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú a máa la ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ àfi ìyàwó rẹ tí ó máa wà nínú àwọn olùṣẹ́kù-lẹ́yìn sínú ìparun.”

[34] Dájúdájú a máa sọ ìyà kan kalẹ̀ lé àwọn ará ìlú yìí lórí láti inú sánmọ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́

[35] Dájúdájú A ti fi àmì kan t’ó fojú hàn lélẹ̀ nínú rẹ̀ fún ìjọ t’ó ní làákàyè

[36] A tún ránṣẹ́ sí ará ìlú Mọdyan. (A rán) arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb (níṣẹ́ sí wọn). Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ retí Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.”

[37] Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn

[38] (A tún ránṣẹ́ sí àwọn) ará ‘Ād àti ará Thamūd. (Ìparun wọn) sì kúkú ti fojú hàn kedere si yín nínú àwọn ibùgbé wọn. Èṣù ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì ṣẹ́rí wọn kúrò nínú ẹ̀sìn (Allāhu). Wọ́n sì jẹ́ olùríran (nípa ọ̀rọ̀ ayé)

[39] (A tún ránṣẹ́ sí àwọn) Ƙọ̄rūn, Fir‘aon àti Hāmọ̄n. Dájúdájú (Ànábì) Mūsā mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Wọ́n sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Wọn kò sì lè mórí bọ́ nínú ìyà

[40] A sì mú ìkọ̀ọ̀kan wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó wà nínú wọn, ẹni tí A fi òkúta iná ránṣẹ́ sí. Ó wà nínú wọn ẹni tí igbe líle gbá mú. Ó wà nínú wọn ẹni tí A jẹ́ kí ilẹ̀ gbémì. Ó sì wà nínú wọn ẹni tí A tẹ̀rì sínú omi. Allāhu kò sì níí ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí

[41] Àpèjúwe àwọn t’ó mú àwọn (òrìṣà) ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Allāhu, ó dà bí àpèjúwe aláǹtàakùn tí ó kọ́ ilé kan. Dájúdájú ilé tí ó yẹpẹrẹ jùlọ ni ilé aláǹtàakùn, tí wọ́n bá mọ̀

[42] Dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[43] Àwọn àkàwé wọ̀nyí, tí À ń fún àwọn ènìyàn, kò sì sí ẹni tí ó máa ṣe làákàyè nípa rẹ̀ àfi àwọn onímọ̀

[44] Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[45] Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà. Kí o sì kírun. Dájúdájú ìrun kíkí ń kọ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú. Àti pé ìrántí Allāhu tóbi jùlọ. Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe. bí ìrun kíkí ṣe ní ẹ̀san bẹ́ẹ̀ náà ló tún jẹ́ ohun t’ó ń mú olùkírun jìnnà sí ìwà aburú ààwẹ̀ gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ìrun kíkí àti ààwẹ̀ gbígbà tì nípasẹ̀ fífún gbólóhùn yìí ní ìtúmọ̀ òdì ó ti kó ìparun bá ẹ̀mí ara rẹ̀ ní ìbámu sí sūrah al-Muddaththir; 74: 42-43. Kí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) là wá nínú èyí

[46] Ẹ má ṣe bá ahlul-kitāb ṣàríyàn jiyàn àfi ní ọ̀nà t’ó dára jùlọ (èyí ni lílo al-Ƙur’ān àti hadīth. Ẹ má sì ṣe jà wọ́n lógun) àfi àwọn t’ó bá ṣàbòsí nínú wọn. Kí ẹ sì sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ẹ̀yin. Ọlọ́hun wa àti Ọlọ́hun yín, (Allāhu) Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”

[47] Báyẹn ni A ṣe sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ. Nítorí náà, àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n gbà á gbọ́. Ó sì wà nínú àwọn wọ̀nyí (ìyẹn, àwọn ará Mọkkah), ẹni t’ó gbà á gbọ́. Kò sì sí ẹni t’ó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn aláìgbàgbọ́

[48] Ìwọ kò ké tírà kan rí ṣíwájú al-Ƙur’ān, ìwọ kò sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ kọ n̄ǹkan rí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, kí àwọn òpùrọ́ ṣeyèméjì (sí al-Ƙur’ān)

[49] Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó. al-Ƙur’ān), òhun ni àwọn āyah t’ó yanjú nínú igbá-àyà àwọn tí A fún ní ìmọ̀-ẹ̀sìn. Kò sì sí ẹni t’ó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn alábòsí

[50] Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ àwọn àmì (ìyanu) kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà lọ́dọ̀ Rẹ̀. Àti pé olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni èmi.”

[51] Ṣé kò tó fún wọn (ní àmì ìyanu) pé A sọ tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ, tí wọ́n ń ké e fún wọn? Dájúdájú ìkẹ́ àti ìṣítí wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó gbàgbọ́

[52] Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Ó mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn t’ó gba irọ́ gbọ́, tí wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò

[53] Wọ́n sì ń kán ọ lójú nípa ìyà! Tí kò bá jẹ́ pé ó ti ní gbèdéke àkókò kan ni, ìyà náà ìbá kúkú dé bá wọn. (Ìyà) ìbá dé bá wọn ní òjijì sẹ́, wọn kò sì níí fura

[54] Wọ́n ń kán ọ lójú nípa ìyà! Dájúdájú iná Jahanamọ kúkú máa yí àwọn aláìgbàgbọ́ po

[55] (Rántí) ọjọ́ tí ìyà yóò bò wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn àti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, (Allāhu) sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ (ìyà) ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò.”

[56] Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ilẹ̀ Mi gbòòrò. Nítorí náà, Èmi nìkan ni kí ẹ jọ́sìn fún

[57] Gbogbo ẹ̀mí l’ó máa tọ́ ikú wò. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni wọn yóò da yín padà sí

[58] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọn sínú àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gígá kan nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere sì dára

[59] (Àwọn ni) àwọn t’ó ṣe sùúrù. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé

[60] Mélòó mélòó nínú àwọn ẹranko tí kò lè dá bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀ gbé, tí Allāhu sì ń ṣe ìjẹ-ìmu fún àwọn àti ẹ̀yin. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[61] Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo

[62] Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[63] Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí Ó fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ó ti kú?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.”

[64] Kí ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìranù àti eré ṣíṣe. Àti pé dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn sì ni ìṣẹ̀mí gbére tí wọ́n bá mọ̀

[65] Nígbà tí wọ́n bá gun ọkọ̀ ojú-omi, wọ́n yóò pe Allāhu (gẹ́gẹ́ bí) olùṣàfọ̀mọ́-àdúà fún Un. Àmọ́ nígbà tí Ó bá kó wọn yọ sí orí ilẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa ṣẹbọ

[66] nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè jayékáyé. Nítorí náà, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀

[67] Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa ṣe Haram (Mọkkah) ni àyè ìfàyàbalẹ̀, tí wọ́n sì ń jí àwọn ènìyàn gbé lọ ní àyíká wọn? Ṣé irọ́ ni wọn yóò gbàgbọ́, tí wọn yó sì ṣàì moore sí ìdẹ̀ra Allāhu

[68] Ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tàbí t’ó pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé inú iná Jahanamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni

[69] Àwọn t’ó gbìyànjú nípa Wa, dájúdájú A máa fi wọ́n mọ àwọn ọ̀nà Wa. Àti pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olúṣe-rere

Àwọn ará Róòmù

Surah 30

[1] ’Alif lām mīm

[2] Wọ́n ṣẹ́gun Rōmu

[3] ní àwọn ilẹ̀ t’ó wà nítòsí (erékùsù Lárúbáwá). Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wọn, àwọn náà máa ṣẹ́gun wọn

[4] ní ọdún mẹ́wàá (sí ìgbà náà). Ti Allāhu ni àṣẹ ní ìṣaájú àti ní ìkẹ́yìn. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo máa dunnú

[5] sí àrànṣe Allāhu. Ó ń ṣàrànṣe fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[6] (Èyí jẹ́) àdéhùn Allāhu. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀

[7] Wọ́n nímọ̀ nípa gban̄gba nínú ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Afọ́nú-fọ́ra sì ni wọ́n nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[8] Ṣé wọn kò ronú nípa ọ̀rọ̀ ara wọn ni? Allāhu kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn

[9] Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n fi ilẹ̀ dáko. Wọ́n sì lo ilẹ̀ fún ohun tí ó pọ̀ ju bí (àwọn ará Mọkkah) ṣe lò ó. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sì mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nítorí náà, Allāhu kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí

[10] Lẹ́yìn náà, aburú jẹ́ àtubọ̀tán àwọn t’ó ṣaburú nítorí pé wọ́n pe àwọn āyah Allāhu nírọ́. Wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́

[11] Allāhu ń pilẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sípò alààyè). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí

[12] Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yó sọ̀rètí nù

[13] Àti pé kò níí sí àwọn olùṣìpẹ̀ fún wọn nínú àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì máa jẹ́ alátakò òrìṣà wọn

[14] Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ yẹn ni wọn yóò pínyà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

[15] Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, wọn yóò wà ní àyè t’ó rẹwà jùlọ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí wọn yó sì máa dunnú

[16] Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pé àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò kó wá sínú Iná

[17] Nítorí náà, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu nígbà tí ẹ bá wà ní alẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní òwúrọ̀

[18] TiRẹ̀ sì ni ọpẹ́ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ní àṣálẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní ọ̀sán

[19] (Allāhu) ń yọ alààyè jáde láti ara òkú. Ó ń yọ òkú jáde láti ara alààyè. Ó ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Báyẹn ni A óò ṣe mu ẹ̀yin náà jáde

[20] Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà náà ẹ̀yin di abara tí ẹ̀ ń fọ́nká (lórí ilẹ̀ ayé)

[21] Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá àwọn aya fun yín láti ara yín nítorí kí ẹ lè rí ìfàyàbalẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ sí ààrin yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó láròjinlẹ̀

[22] Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn èdè yín àti àwọn àwọ̀ ara yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onímọ̀

[23] Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni oorun yín ní alẹ́ àti ní ọ̀sán àti wíwá tí ẹ̀ ń wá nínú oore Rẹ̀ (fún ìjẹ-ìmu). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀

[24] Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni fífi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ti ẹ̀rù àti ìrètí. Ó sì ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó ń fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè

[25] Àti pé nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá pè yín ní ìpè kan nígbà náà ni ẹ̀yin yóò máa jáde láti inú ilẹ̀

[26] TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀

[27] Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀). TiRẹ̀ ni ìròyìn t’ó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[28] (Allāhu) ṣàkàwé kan fun yín nípa ara yín. Ǹjẹ́ ẹ ní akẹgbẹ́ nínú àwọn ẹrú yín lórí ohun tí A fun yín ní arísìkí, tí ẹ jọ máa pín (dúkìá náà) ní dọ́gbadọ́gba, tí ẹ ó sì máa páyà wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń páyà ẹ̀yin náà? Báyẹn ni A ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè

[29] Ńṣe ni àwọn t’ó ṣàbòsí tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn láì sí ìmọ̀ kan (fún wọn). Ta sì ni ó lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà? Kò sì níí sí àwọn alárànṣe fún wọn

[30] Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sì sí ìyípadà fún ẹ̀dá Allāhu. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀

[31] (Ẹ jẹ́) olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Ẹ páyà Rẹ̀. Ẹ kírun. Ẹ má ṣe wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ

[32] (Ẹ má ṣe wà) nínú àwọn t’ó dá ẹ̀sìn wọn sí kélekèle, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tí ó wà lọ́dọ̀ wọn

[33] Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, wọn yóò pe Olúwa wọn, tí wọn yóò máa ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí (Allāhu) bá fún wọn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn

[34] nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí ohun tí (Allāhu) fún wọn. Ẹ máa jayé lọ. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀

[35] Tàbí A sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún wọn, t’ó ń sọ̀rọ̀ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀

[36] Nígbà tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò, wọn yóò dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn wọ́n nípa ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú, nígbà náà ni wọn yóò sọ̀rètí nù

[37] Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́, (Ó sì ń) díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́)? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó gbàgbọ́

[38] Nítorí náà, fún ẹbí ni ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò tí agara dá (ní n̄ǹkan). Ìyẹn lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń fẹ́ Ojú rere Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè

[39] Ohunkóhun tí ẹ bá fún (àwọn ènìyàn) ní ẹ̀bùn, nítorí kí ó lè di èlé láti ara dúkìá àwọn ènìyàn, kò lè lékún ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì (fún àwọn ènìyàn) ní Zakāh, tí ẹ̀ ń fẹ́ ojú rere Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní àdìpèlé ẹ̀san

[40] Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín, lẹ́yìn náà, Ó fun yín ní arísìkí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà, O máa sọ yín di alààyè. Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè ṣe n̄ǹkan kan nínú ìyẹn? Mímọ́ ni fún Un. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[41] Ìbàjẹ́ hàn lórí ilẹ̀ àti lójú omi nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ṣe níṣẹ́ (aburú) nítorí kí (Allāhu) lè fi (ìyà) apá kan èyí tí wọ́n ṣe níṣẹ́ (aburú) tọ́ wọn lẹ́nu wò nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (níbi aburú)

[42] Sọ pé: “Ẹ rìn lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn t’ó ṣíwájú ṣe rí! Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n jẹ́ ọ̀ṣẹbọ.”

[43] Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀ ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò sí n̄ǹkan tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ènìyàn yóò pínyà sí (èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò Iná)

[44] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, orí ara rẹ̀ ni (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń tẹ́ ìtẹ́ (Ọgbà Ìdẹ̀ra) sílẹ̀ fún

[45] nítorí kí (Allāhu) lè san ẹ̀san rere nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́

[46] Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé, Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró ìdùnnú. Àti pé nítorí kí (Allāhu) lè fun yín tọ́ wò nínú ìkẹ́ Rẹ̀; àti nítorí kí ọkọ̀ ojú-omi lè rìn lójú-omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́

[47] Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. A sì gbẹ̀san lára àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún wa láti ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[48] Allāhu ni Ẹni t’Ó ń fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tu ẹ̀ṣújò sókè. (Allāhu) yó sì tẹ́ (ẹ̀ṣújò) sílẹ̀ s’ójú sánmọ̀ bí Ó bá ṣe fẹ́. Ó sì máa dá a kélekèle (sí ojú sánmọ̀). O sì máa rí òjò tí ó ma máa jáde láààrin rẹ̀. Nígbà tí Ó bá sì rọ (òjò náà) fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, nígbà náà wọn yó sì máa dunnú

[49] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí Ó tó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún wọn, wọ́n ti sọ̀rètí nù ṣíwájú rẹ̀

[50] Nítorí náà, wòye sí àwọn orípa ìkẹ́ Allāhu, (wo) bí (Allāhu) ṣe ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú (Allāhu) yìí ni Ó kúkú máa sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[51] Dájúdájú tí A bá rán atẹ́gùn kan (sí wọn), kí wọ́n sì rí (n̄ǹkan ọ̀gbìn wọn) ní pípọ́n (jíjóná), dájúdájú wọn yó sì máa ṣàì moore lọ lẹ́yìn rẹ̀

[52] Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ

[53] Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́. Àwọn sì ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan tí Allāhu kò fún ní iṣẹ́ ìyanu kan tàbí òmíràn ṣe ní ìbámu sí ìgbà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni èyíkéyìí iṣẹ́ ìyanu tí ó bá tọwọ́ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan wáyé kò sọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ náà di olúwa àti olùgbàlà. Allāhu nìkan ṣoṣo ní Olúwa àti Olùgbàlà ayé àti ọ̀run. Nítorí náà fún àlékún lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tí Allāhu bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àmọ́ àwọn kristiẹni gẹ́gẹ́ bí ìṣesí wọn bí ó ṣe ń wù ú tó àti bí ó ṣe ń jẹ̀rankàn tó ni pé kí gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ gbàgbọ́ nínú Allāhu. Àmọ́ wọn kò gbàgbọ́

[54] Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti (ara n̄ǹkan) lílẹ, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn lílẹ Ó fun (yín ní) agbára, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn agbára, Ó tún fi lílẹ àti ogbó (si yín lára). Ó ń dá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Onímọ̀, Alágbára

[55] Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá ṣẹlẹ̀ (ìyẹn, ọjọ́ Àjíǹde), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò máa búra pé àwọn kò gbé (ilé ayé) ju àkókò kan lọ.” Báyẹn ni wọ́n ṣe máa ń f’irọ́ tanra wọn jẹ

[56] Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ òdodo yóò sọ pé: “Dájúdájú nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu, ẹ ti gbé ilé ayé títí Ọjọ́ Àjíǹde (fi tó). Nítorí náà, èyí ni Ọjọ́ Àjíǹde, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀.”

[57] Nítorí náà ní ọjọ́ yẹn, àwọn t’ó ṣàbòsí, àwáwí wọn kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu

[58] A kúkú ti fi oríṣiríṣi àkàwé lélẹ̀ nínú al-Ƙur’ān yìí fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú tí o bá mú āyah kan wá fún wọn, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Ẹ̀yin (mùsùlùmí) kò jẹ́ kiní kan tayọ òpùrọ́.”

[59] Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí dí ọkàn àwọn tí kò nímọ̀

[60] Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí kò mọ àmọ̀dájú (nípa Ọjọ́ ẹ̀san) sọ ọ́ dòpè

Luqmānì

Surah 31

[1] ’Alif lām mīm

[2] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà ọgbọ́n

[3] (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún àwọn olùṣe-rere

[4] àwọn t’ó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[5] Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni àwọn olùjèrè

[6] Ó wà nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń ra ìranù-ọ̀rọ̀ láti fi ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àìnímọ̀ àti nítorí kí ó lè sọ ẹ̀sìn di yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún

[7] Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa pẹ̀yìndà ní ti ìgbéraga, àfi bí ẹni pé kò gbọ́ ọ, àfi bí ẹni pé èdídí wà nínú etí rẹ̀ méjèèjì. Nítorí náà, fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[8] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn

[9] Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) àdéhùn tí Allāhu ṣe ní ti òdodo. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[10] Ó dá àwọn sánmọ̀ láì ní òpó tí ẹ lè rí. Ó sì ju àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ yín lẹ́sẹ̀. Ó fọ́n gbogbo n̄ǹkan abẹ̀mí ká sórí ilẹ̀. A tún sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, A sì fi mú gbogbo oríṣiríṣi èso dáadáa hù jáde láti inú ilẹ̀

[11] Èyí ni ẹ̀dá ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ fi ohun tí àwọn mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ dá hàn mí! Rárá o! Àwọn alábòsí wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé ni

[12] Dájúdájú A ti fún Luƙmọ̄n ní ọgbọ́n, pé: “Dúpẹ́ fún Allāhu.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́, ó ń dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́ (tí ọpẹ́ tọ́ sí)

[13] (Rántí) nígbà tí Luƙmọ̄n sọ fún ọmọ rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe wáàsí fún un, pé: “Ọmọ mi, má ṣe ṣẹbọ sí Allāhu. Dájúdájú ẹbọ ṣíṣe ni àbòsí ńlá

[14] Àti pé A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn nípa àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì - ìyá rẹ̀ gbé e ká (nínú oyún) pẹ̀lú àìlera lórí àìlera, ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ láààrin ọdún méjì – (A sọ) pé: “Dúpẹ́ fún Èmi àti àwọn òbí rẹ méjèèjì.” Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[15] Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì.1 Fi dáadáa bá àwọn méjèèjì lò pọ̀ ní ilé ayé.2 Kí o sì tẹ̀lé ojú ọ̀nà ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Mi (ní ti ìronúpìwàdà). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. n̄ǹkan dáadáa ni. Ìkẹta: ohunkóhun tí àṣà àti ìṣe ẹ̀yà ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan bá pè ní dáadáa n̄ǹkan dáadáa ni ní òdiwọ̀n ìgbà tí āyah kan tàbí hadīth kan kò bá ti lòdì sí irúfẹ́ n̄ǹkan náà. Bí àpẹẹrẹ

[16] Ọmọ mi, dájúdájú tí ó bá jẹ́ pé òdiwọ̀n èso kardal kan ló wà nínú àpáta, tàbí nínú àwọn sánmọ̀, tàbí nínú ilẹ̀, Allāhu yóò mú un wá. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán

[17] Ọmọ mi, kírun, p’àṣẹ rere, kọ aburú, kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ọ. Dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ t’ó pọn dandan

[18] Má ṣe kọ párìkẹ́ rẹ sí ènìyàn. Má sì ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú fáàrí. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn gbogbo onígbèéraga, onífáàrí

[19] Jẹ́ kí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì, kí o sì rẹ ohùn rẹ nílẹ̀. Dájúdájú ohùn t’ó burú jùlọ mà ni ohùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

[20] Ṣé ẹ ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ fun yín, Ó sì pé àwọn ìkẹ́ Rẹ̀ fun yín ní gban̄gba àti ní kọ̀rọ̀? Ó sì wà nínú àwọn ènìyàn ẹni t’ó ń jiyàn nípa Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (nínú sunnah Ànábì s.a.w.) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) t’ó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn)

[21] Nígbà tí wọ́n bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá! A máa tẹ̀lé ohun tí a bá lọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni.” (Ṣé wọn yóò tẹ̀lé àwọn bàbá wọn) t’òhun ti bí Èṣù ṣe ń pè wọ́n síbi ìyà Iná t’ó ń jò fòfò

[22] Ẹnikẹ́ni tí ó bá jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, tí ó jẹ́ olùṣe-rere, dájúdájú onítọ̀un ti dìrọ̀ mọ́ okùn t’ó fọkàn balẹ̀ jùlọ. Àti pé ọ̀dọ̀ Allāhu ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)

[23] Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, má ṣe jẹ́ kí àìgbàgbọ́ rẹ̀ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Nígbà náà, A máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[24] A máa fún wọn ní ìgbádùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, A máa taari wọn sínú ìyà t’ó nípọn

[25] Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ̀

[26] Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́

[27] Tí ó bá jẹ́ pé kìkìdá ohun t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ní igi ni gègé ìkọ̀wé, kí agbami odò jẹ́ tàdáà rẹ̀, agbami odò méje (tún wà) lẹ́yìn rẹ̀ (t’ó máa kún un), àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu kò níí tán (lẹ́yìn tí àwọn n̄ǹkan ìkọ̀wé wọ̀nyí bá tán nílẹ̀). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[28] Ìṣẹ̀dá yín àti àjíǹde yín kò tayọ bí (ìṣẹ̀dá àti àjíǹde) ẹ̀mí ẹyọ kan. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran

[29] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán, Ó ń ti ọ̀sán bọ inú òru, Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá? Ìkọ̀ọ̀kan wọn sì ń rìn títí di gbèdéke àkókò kan. Àti pé (ṣé o ò rí i pé) dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[30] Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Ó ga, Ó tóbi

[31] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú ọkọ̀ ojú-omi ń rìn ní ojú omi pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ̀, (ṣebí) nítorí kí (Allāhu) lè fi hàn yín nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́

[32] Nígbà tí ìgbì omi bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru bí àwọn àpáta àti ẹ̀ṣújò, wọ́n á pe Allāhu (gẹ́gẹ́ bí) olùṣàfọ̀mọ́-àdúà fún Un. Nígbà tí Ó bá sì gbà wọ́n là sórí ilẹ̀, onídéédé sì máa wà nínú wọn. Kò sì sí ẹni t’ó máa tako àwọn āyah Wa àfi gbogbo ọ̀dàlẹ̀, aláìmoore

[33] Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Kí ẹ sì páyà ọjọ́ kan tí òbí kan kò níí ṣàǹfààní fún ọmọ rẹ̀; àti pé ọmọ kan, òun náà kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún òbí rẹ̀. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Nítorí náà, ìṣẹ̀mí ayé yìí kò gbọdọ̀ tàn yín jẹ. (Èṣù) ẹlẹ́tàn kò sì gbọdọ̀ tàn yín jẹ nípa Allāhu

[34] Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ó ń sọ òjò kalẹ̀. Ó mọ ohun t’ó wà nínú àpòlùkẹ́. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ohun tí ó máa ṣe níṣẹ́ ní ọ̀la. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán

Ìforíbalẹ̀

Surah 32

[1] ’Alif lām mīm

[2] Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀ (pé ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[3] Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ rẹ̀ ni.” Rárá o! Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè fi ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá wọn rí ṣíwájú rẹ, nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà

[4] Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Kò sí aláàbò àti olùṣìpẹ̀ kan fun yín lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni

[5] Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) láti sánmọ̀ wá sórí ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (àbọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) yóò gùnkè tọ̀ Ọ́ lọ láààrin ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ọdún nínú òǹkà tí ẹ̀ ń kà

[6] Ìyẹn ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[7] Ẹni t’ó ṣe gbogbo n̄ǹkan tí Ó dá ní dáadáa. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ènìyàn láti inú erùpẹ̀ amọ̀

[8] Lẹ́yìn náà, Ó ṣe àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ láti ara ohun tí A mú jáde láti ara omi lílẹ yẹpẹrẹ

[9] Lẹ́yìn náà, Ó to (oríkèéríkèé) rẹ̀ dọ́gba. Ó sì fẹ́ (ẹ̀mí) sí i lára nínú ẹ̀mí Rẹ̀ (tí Ó dá). Ó tún ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fun yín. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá

[10] Wọ́n sì wí pé: “Ǹjẹ́ nígbà tí a bá ti pòórá sínú ilẹ̀, ǹjẹ́ àwa tún lè wà ní ẹ̀dá titun mọ́? Àní sẹ́, àwọn ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn

[11] Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A fi tì yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.” gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Kò sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ìṣẹ̀mí wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Kò sì sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ikú wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Nípa èyí Allāhu l’Ó ń fi àṣẹ Rẹ̀ gba ẹ̀mí kúrò lára ẹ̀dá Rẹ̀ ní àkókò tí Ó ti kọ mọ́ ọn nínú kádàrá. Ìyẹn ni ó jẹyọ nínú sūrah az-Zumọr; 39:42. Bákan náà

[12] (Ìwọ ìbá rí èèmọ̀) tí ó bá jẹ́ pé o rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá sorí kọ́ ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (wọ́n sì máa wí pé): “Olúwa wa, a ti ríran, a sì ti gbọ́ràn (báyìí), nítorí náà, dá wa padà (sí ilé ayé) nítorí kí á lè lọ ṣe iṣẹ́ rere; dájúdájú àwa ni alámọ̀dájú.”

[13] Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ.”

[14] Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ti gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Dájúdájú Àwa náà yóò gbàgbé yín sínú Iná. Ẹ tọ́ ìyà gbére wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[15] Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga

[16] Wọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn kúrò lórí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn

[17] Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere)

[18] Ǹjẹ́ ẹni t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni t’ó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba

[19] Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere)

[20] Ní ti àwọn t’ó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè nírọ́ wò.”

[21] Dájúdájú A máa fún wọn tọ́ wò nínú ìyà t’ó kéré jùlọ (nílé ayé) yàtọ̀ sí ìyà t’ó tóbi jùlọ (lọ́run) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo ṣíwájú ikú wọn)

[22] Àti pé ta l’ó ṣe àbòsí t’ó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

[23] Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí ó ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀). A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl

[24] Àti pé A ṣe àwọn aṣíwájú kan nínú wọn ní afinimọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù. Wọ́n sì ń ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa

[25] Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí

[26] Ṣé kò fojú hàn sí wọn pé, mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Àwọn náà sì ń rìn kọjá nínú àwọn ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Nítorí náà, ṣé wọn kò níí tẹ́tí gbọ́rọ̀ (òdodo ni)

[27] Tàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni

[28] Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

[29] Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ wọn kò níí ṣàǹfààní fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (nínú Allāhu). A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).”

[30] Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì máa retí (Ọjọ́ Ìdájọ́). Dájúdájú àwọn náà ń retí (rẹ̀)

Àwọn ẹgbẹ́

Surah 33

[1] Ìwọ Ànábì, bẹ̀rù Allāhu. Má sì tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[2] Tẹ̀lé ohun tí A ń mú wá fún ọ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[3] Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́

[4] Allāhu kò fún ènìyàn kan ní ọkàn méjì nínú ikùn rẹ̀. (Allāhu) kò sì sọ àwọn ìyàwó yín, tí ẹ̀ ń fi ẹ̀yìn wọn wé ẹ̀yìn ìyá yín, di ìyá yín. Àti pé (Allāhu) kò sọ àwọn ọmọ-ọlọ́mọ tí ẹ̀ ń pè ní ọmọ yín di ọmọ yín. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ ẹnu yín. Allāhu ń sọ òdodo. Àti pé Òun l’Ó ń fi (ẹ̀dá) mọ̀nà

[5] Ẹ pè wọ́n pẹ̀lú orúkọ bàbá wọn. Òhun l’ó ṣe déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n tí ẹ ò bá mọ (orúkọ) bàbá wọn, ọmọ ìyá yín nínú ẹ̀sìn àti ẹrú yín kúkú ni wọ́n. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ bá ṣàṣìṣe rẹ̀, ṣùgbọ́n (ẹ̀ṣẹ̀ wà níbi) ohun tí ọkàn yín mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[6] Ànábì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo ju ẹ̀mí ara wọn lọ (nípa ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀). Àwọn aya rẹ̀ sì ni ìyá wọn. Nínú Tírà Allāhu, àwọn ẹbí, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ ju apá kan lọ. (Àwọn ẹbí tún ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ) ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn t’ó kúrò nínú ìlú Mọkkah fún ààbò ẹ̀sìn, àfi tí ẹ bá máa ṣe dáadáa kan sí àwọn ọ̀rẹ́ yín (wọ̀nyí ni ogún lè fi kàn wọ́n pẹ̀lú àsọọ́lẹ̀). Ìyẹn wà nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ) ní àkọsílẹ̀

[7] (Rántí) nígbà tí A gba àdéhùn ní ọwọ́ àwọn Ànábì àti ní ọwọ́ rẹ, àti ní ọwọ́ (Ànábì) Nūh, ’Ibrọ̄hīm, Mūsā àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. A gba àdéhùn ní ọwọ́ wọn ní àdéhùn t’ó nípọn

[8] nítorí kí (Allāhu) lè bèèrè (òdodo) àwọn olódodo nípa òdodo wọn. Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[9] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín, nígbà tí àwọn ọmọ ogun (oníjọ) dé ba yín. A sì rán atẹ́gùn àti àwọn ọmọ ogun tí ẹ ò fójú rí sí wọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe

[10] (Ẹ rántí) nígbà tí wọ́n dé ba yín láti òkè yín àti ìsàlẹ̀ yín, àti nígbà tí àwọn ojú yẹ̀ (sọ́tùn-ún sósì), tí àwọn ọkàn sí dé ọ̀nà-ọ̀fun (ní ti ìpáyà). Ẹ sì ń ro àwọn èrò kan nípa Allāhu

[11] Níbẹ̀ yẹn ni wọ́n ti fi àdánwò kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọ́n sì milẹ̀ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ní ìmìtìtì líle

[12] (Ẹ rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àìsàn wà nínú ọkàn wọn ń wí pé: “Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kò ṣe àdéhùn kan fún wa bí kò ṣe ẹ̀tàn.”

[13] (Ẹ rántí) nígbà tí igun kan nínú wọn wí pé: “Ẹ̀yin ará Yẹthrib, kò sí àyè (ìṣẹ́gun) fun yín, nítorí náà, ẹ ṣẹ́rí padà (lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́).” Apá kan nínú wọn sì ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ Ànábì, wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú ilé wa dá páropáro ni.” (Ilé wọn) kò sì dá páropáro. Wọn kò sì gbèrò ohun kan tayọ síságun

[14] Àti pé tí ó bá jẹ́ pé (ọmọ ogun oníjọ) wọlé tọ̀ wọ́n wá láti àwọn ìloro ìlú (Mọdīnah), lẹ́yìn náà, kí wọ́n pe (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) sínú ẹbọ ṣíṣe, wọn ìbá ṣẹbọ. Wọn kò sì níí gbé nínú ìlú mọ́ tayọ ìgbà díẹ̀ (tí wọn yóò fi parẹ́)

[15] Dájúdájú wọ́n ti bá Allāhu ṣe àdéhùn ṣíwájú pé àwọn kò níí pẹ̀yìndà (láti ságun). Àdéhùn Allāhu sì jẹ́ ohun tí wọ́n máa bèèrè (lọ́wọ́ wọn)

[16] Sọ pé: “Síságun yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí ẹ bá sá fún ikú tàbí pípa (sí ojú ogun ẹ̀sìn. Tí ẹ bá sì ságun) nígbà náà, A ò níí fun yín ní ìgbádùn ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀

[17] Sọ pé: “Ta ni ẹni tí ó lè dá ààbò bò yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá fẹ́ fi aburú kàn yín tàbí tí Ó bá fẹ́ kẹ yín?” Wọn kò sì lè rí aláàbò tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu

[18] Dájúdájú Allāhu ti mọ àwọn t’ó ń fa ènìyàn sẹ́yìn nínú yín àti àwọn t’ó ń wí fún àwọn arakùnrin wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa.” Wọn kò sì níí lọ sí ojú ogun ẹ̀sìn àfi (ogun) díẹ̀

[19] Wọ́n ní ahun si yín (láti ṣe ìrànlọ́wọ́). Nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá dé, o máa rí wọn tí wọn yóò máa wò ọ́. Ojú wọn yó sì máa yí kiri ràkọ̀ràkọ̀ (ní ti ìbẹ̀rù) bí ẹni tí ó fẹ́ dákú, ṣùgbọ́n nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá lọ, (tí ìkógun bá dé), wọn yóò máa fi àwọn ahọ́n kan t’ó mú bérébéré ba yín sọ̀rọ̀ ní ti ṣíṣe ọ̀kánjúà sí oore náà. Àwọn wọ̀nyẹn kò gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu

[20] Wọ́n ń lérò pé àwọn ọmọ ogun oníjọ kò tí ì lọ, (wọ́n sì ti túká). Tí àwọn ọmọ ogun oníjọ bá (sì padà) dé, dájúdájú (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò fẹ́ kí àwọn ti wà ní oko láààrin àwọn Lárúbáwá oko, kí wọ́n máa bèèrè nípa àwọn ìró yín (pé ṣé ẹ ti kú tán tàbí ẹ sì wà láyé). Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n wà láààrin yín, wọn kò níí jagun bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀

[21] Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere wà fun yín lára Òjíṣẹ́ Allāhu fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí (ẹ̀san) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (ìgbà)

[22] Nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo rí àwọn ọmọ ogun oníjọ, wọ́n sọ pé: “Èyí ni ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní àdéhùn fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ti sọ òdodo ọ̀rọ̀.” (Rírí wọn) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe (àlékún) ìgbàgbọ́ òdodo àti ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ (fún àṣẹ Allāhu)

[23] Ó wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n jẹ́ olódodo nípa àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe; ó wà nínú wọn ẹni tí ó pé àdéhùn rẹ̀ (t’ó sì kú sójú ogun ẹ̀sìn), ó sì wà nínú wọn ẹni t’ó ń retí (ikú tirẹ̀). Wọn kò sì yí (àdéhùn) padà rárá

[24] (Ìwọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi (òdodo) àwọn olódodo san wọ́n ní ẹ̀san òdodo wọn, àti nítorí kí Ó lè jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìyà tí Ó bá fẹ́ tàbí nítorí kí Ó lè gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[25] Allāhu sì dá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ padà tòhun ti ìbínú wọn; ọwọ́ wọn kò sì tẹ oore kan. Allāhu sì tó àwọn onígbàgbọ́ òdodo níbi ogun náà. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Olùborí

[26] (Allāhu) sì mú àwọn t’ó ṣèrànlọ́wọ́ fún (àwọn ọmọ ogun oníjọ) nínú àwọn ahlul-kitāb sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú àwọn odi wọn. Ó sì ju ẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Ẹ̀ ń pa igun kan (nínú wọn), ẹ sì ń kó igun kan lẹ́rú

[27] (Allāhu) sì jogún ilẹ̀ wọn, ilé wọn, dúkìá wọn àti ilẹ̀ tí ẹ ò tẹ̀ rí fun yín. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[28] Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn ìyàwó rẹ pé: “Tí ẹ bá fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ẹ wá níbí kí n̄g fun yín ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀, kí n̄g sì fi yín sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ t’ó rẹwà

[29] Tí ẹ bá sì fẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ilé Ìkẹ́yìn, dájúdájú Allāhu ti pèsè ẹ̀san ńlá sílẹ̀ de àwọn olùṣe-rere lóbìnrin nínú yín.”

[30] Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe ìbàjẹ́ t’ó fojú hàn, A máa di àdìpèlé ìyà ìlọ́po méjì fún un. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu

[31] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nínú yín, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ rere, A máa fún un ní ẹ̀san ìlọ́po méjì. A sì ti pèsè ìjẹ-ìmu alápọ̀n-ọ́nlé sílẹ̀ dè é.”

[32] Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹ ò dà bí ẹnì kan kan nínú àwọn obìnrin, tí ẹ bá ti bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ má ṣe dínhùn (sí àwọn ọkùnrin létí) nítorí kí ẹni tí àrùn wà nínú ọkàn rẹ̀ má baá jẹ̀rankàn. Kí ẹ sì máa sọ ọ̀rọ̀ t’ó dára

[33] Ẹ fìdí mọ́lé yín. Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ t’ó di mùsùlùmí). Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu kàn ń gbèrò láti mú ẹ̀gbin kúrò lára yín, ẹ̀yin ará ilé (Ànábì). Àti pé Ó (kàn ń gbèrò láti) fọ̀ yín mọ́ tónítóní ni

[34] Ẹ rántí ohun tí wọ́n ń ké nínú ilé yín nínú àwọn āyah Allāhu àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah Ànábì). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀. tí Lárúbáwá bá ń d’ojú ọ̀rọ̀ kọ ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ tàbí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ èdè Lárúbáwá ti ní ìhun akọ fún akọ. Bákan náà

[35] Dájúdájú àwọn mùsùlùmí lọ́kùnrin àti mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lóbìnrin, àwọn olódodo lọ́kùnrin àti àwọn olódodo lóbìnrin, àwọn onísùúrù lọ́kùnrin àti àwọn onísùúrù lóbìnrin, àwọn olùpáyà Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùpáyà Allāhu lóbìnrin, àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, àwọn aláàwẹ̀ lọ́kùnrin àti àwọn aláàwẹ̀ lóbìnrin, àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lọ́kùnrin àti àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lóbìnrin, àwọn olùrántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́kùnrin àti àwọn olùrántí Allāhu (ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀) lóbìnrin; Allāhu ti pèsè àforíjìn àti ẹ̀san ńlá sílẹ̀ dè wọ́n

[36] Kò tọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, nígbà tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ bá ti parí ọ̀rọ̀ kan, láti ní ẹ̀ṣà (ọ̀rọ̀ mìíràn) fún ọ̀rọ̀ ara wọn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé

[37] (Rántí) nígbà tí ò ń sọ fún ẹni tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún, tí ìwọ náà ṣèdẹ̀ra fún1 pé: “Mú ìyàwó rẹ dání, kí o sì bẹ̀rù Allāhu.” O sì ń fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ ohun tí Allāhu yó ṣàfi hàn rẹ̀. Àti pé ò ń páyà àwọn ènìyàn. Allāhu l’Ó sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o páyà Rẹ̀. Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ nítorí kí ó má baà jẹ́ láìfí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti fẹ́ ìyàwó ọmọ-ọlọ́mọ tí wọ́n ń pè ní ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ti parí bùkátà wọn lọ́dọ̀ wọn (tí wọ́n sì ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀). Àṣẹ Allāhu sì gbọ́dọ̀ ṣẹ

[38] Kò sí láìfí fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nípa ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un. (Ó jẹ́) ìlànà Allāhu lórí àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú. Àti pé àṣẹ Allāhu jẹ́ àkọọ́lẹ̀ kan t’ó gbọ́dọ̀ ṣẹ

[39] (Kọ́ṣe àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú nínú àwọn Òjíṣẹ́) àwọn t’ó ń jẹ́ iṣẹ́ Allāhu, tí wọ́n ń páyà Rẹ̀, tí wọn kò sì páyà ẹnì kan àyàfi Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣírò

[40] (Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. òpùrọ́ asòòkùn sẹ́sìn wulẹ̀ ni òun. Irọ́ ẹnu rẹ̀ ti pọ̀ jù. Alágbárí pọ́nńbélé sì ni pẹ̀lú. Irú iṣẹ́ aburú tí ṣeeu Ahmada Tijāni ṣe fún ’Islām gẹ́lẹ́ náà ni mirza ghulam Ahmad ṣe. Àwọn méjèèjì ni Pọ́ọ̀lù láààrin àwa mùsùlùmí. Ẹ wo díẹ̀ nínú irọ́ ńlá rẹ̀. Mirza ghulam Ahmad sọ pé: ""Allāhu sọ fún mi ní èdè Lárúbáwá pé bí ọmọ Mi ló ṣe wà sí Mi."" (Tadhkirah “Tí ó bá jẹ́ pé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun kò yẹ fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti padà wá sáyé mọ́ lópin ayé.” Wọ́n tún sọ pé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun àmọ́ ìṣòro tiwọn ni pé

[41] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí Allāhu ní ìrántí púpọ̀

[42] Ẹ ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́

[43] (Allāhu) Òun ni Ẹni t’Ó ń kẹ yín, àwọn mọlāika Rẹ̀ (sì ń tọrọ àforíjìn fun yín), nítorí kí Allāhu lè mu yín kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àti pé Ó ń jẹ́ Àṣàkẹ́-ọ̀run fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[44] Ìkíni wọn ní ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Rẹ̀ ni "àlàáfíà." Ó sì ti pèsè ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlẹ́ sílẹ̀ dè wọ́n

[45] Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú, olùkìlọ̀

[46] olùpèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ àti àtùpà ìmọ́lẹ̀

[47] Fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú oore àjùlọ ńlá wà fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu

[48] Má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Fi bí wọ́n ṣe ń kó ìnira bá ọ sílẹ̀. Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì ń tó ní Alámòjúútó

[49] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo lọ́kùnrin, nígbà tí ẹ bá fẹ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó bá wọn ní àṣepọ̀ lọ́kọ-láya, kò sí opó ṣíṣe kan tí wọn yóò ṣe fun yín. Nítorí náà, ẹ fún wọn ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀. Kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ t’ó rẹwà

[50] Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún ọ àwọn ìyàwó rẹ̀, tí o fún ní owó-orí wọn, àti àwọn ẹrú nínú àwọn tí Allāhu fí ṣe ìkógun fún ọ àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin bàbá rẹ àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin bàbá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin ìyá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin ìyá rẹ, àwọn t’ó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ìlú Mọdīnah pẹ̀lú rẹ, àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ó bá fi ara rẹ̀ tọrẹ fún Ànábì, tí Ànábì náà sì fẹ́ fi ṣe ìyàwó. Ìwọ nìkan ni (èyí) wà fún, kò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin. A ti mọ ohun tí A ṣe ní ọ̀ran-anyàn fún wọn nípa àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ẹrú wọn. (Èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ó má baà sí láìfí fún ọ. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[51] Lọ́ra láti súnmọ́ ẹni tí o bá fẹ́ nínú wọn. Fa ẹni tí o bá fẹ́ mọ́ra. Àti pé ẹni kẹ́ni tí o bá tún wá (láti súnmọ́) nínú àwọn tí o ò pín oorun fún, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ (láti ṣe bẹ́ẹ̀). Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ojú wọn tutù ìdùnnú. Wọn kò sì níí banújẹ́. Gbogbo wọn yó sì yọ́nú sí ohunkóhun tí o bá fún wọn. Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Aláfaradà

[52] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ (láti fẹ́) àwọn obìnrin (mìíràn) lẹ́yìn (ìsọ̀rí àwọn tí A ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ) láti fi àwọn obìnrin (mìíràn) pààrọ̀ wọn, kódà kí dáadáa wọn jọ ọ́ lójú, àfi àwọn ẹrú rẹ (nìkan l’o lè kọ̀ sílẹ̀ nínú àwọn ìyàwó rẹ). Allāhu sì ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan

[53] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe wọ àwọn inú ilé Ànábì àfi tí wọ́n bá yọ̀ǹda fun yín láti wọlé jẹun láì níí jẹ́ ẹni tí yóò máa retí kí oúnjẹ jinná, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pè yín (fún oúnjẹ) ẹ wọ inú ilé nígbà náà. Nígbà tí ẹ bá sì jẹun tán, ẹ túká, ẹ má ṣe jókòó kalẹ̀ tira yin fún ọ̀rọ̀ kan mọ́ (nínú ilé rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn ń kó ìnira bá Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì ń tijú yín. Allāhu kò sì níí tijú níbi òdodo. Nígbà tí ẹ bá sì fẹ́ bèèrè n̄ǹkan ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó rẹ̀, ẹ bèèrè rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wọn ní ẹ̀yìn gàgá. Ìyẹn jẹ́ àfọ̀mọ́ jùlọ fún ọkàn yín àti ọkàn wọn. Kò tọ́ fun yín láti kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu. (Kò sì tọ́ fun yín) láti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn (ikú) rẹ̀ láéláé. Dájúdájú ìyẹn jẹ́ n̄ǹkan ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu

[54] Tí ẹ bá ṣàfi hàn kiní kan tàbí ẹ fi pamọ́, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[55] Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ìyàwó Ànábì nípa àwọn bàbá wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn arákùnrin wọn àti àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn àti àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn àti àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn àti àwọn ẹrúkùnrin wọn (láti wọlé tì wọ́n.) Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan

[56] Dájúdájú Allāhu àti àwọn mọlāika Rẹ̀ ń kẹ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tọrọ ìkẹ́ fún un, kí ẹ sì kí i ní kíkí àlàáfíà. àwọn Sọhābah náa (r.ahm) máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin náà ẹ wo bí àwọn àáfà sunnah ṣe ń ṣe asọlātu fún Ànábì nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣaájú nínú àwọn tírà wọn. Kò sí aburú nínú èyí rárá. Ṣùgbọ́n mùsùlùmí yóò ṣe àgbékalẹ̀ ìhun asọlātu dáràn tí ó bá fi lè kó sínú ọ̀kan nínú àwọn n̄ǹkan mẹ́fà kan. Ìkíní: Lílo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí òfin àti àdìsọ́kàn ’Islām nínú àwọn gbólóhùn asọlātu náà. Ìkejì: Sísọ gbólóhùn asọlātu yẹn gan-angan di ìlànà tí wọn yóò máa pèpè sí tí irúfẹ́ gbólóhùn náà yóò fi wá dà bí ẹni pé hadīth kan l’ó gbà á wá

[57] Dájúdájú àwọn t’ó ń fi ìnira kan Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn nílé ayé àti ní ọ̀run. Ó sì ti pèsè ìyà t’ó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ dè wọ́n

[58] Àwọn t’ó ń fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin nípa n̄ǹkan tí wọn kò ṣe, dájúdájú wọ́n ti ru ẹrù (ọ̀ràn) ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé

[59] Ìwọ Ànábì sọ fún àwọn ìyàwó rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ àti àwọn obìnrin onígbàgbọ́ òdodo pé kí wọ́n máa gbé àwọn aṣọ jilbāb wọn wọ̀ sí ara wọn bámúbámú. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti fi mọ̀ wọ́n (ní olùbẹ̀rù Allāhu). Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò níí fi ìnira kàn wọ́n. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[60] Tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí, àti àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn túlétúlé nínú ìlú Mọdīnah kò bá jáwọ́ (níbi aburú), dájúdájú A máa dẹ ọ́ sí wọn, (o sì máa borí wọn). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí bá ọ gbé àdúgbò pọ̀ mọ́ àfi fún ìgbà díẹ̀

[61] Wọ́n di ẹni-ìṣẹ́bilé níbikíbi tí ọwọ́ bá ti bà wọ́n; wọ́n máa mú wọn, wọ́n sì máa pa wọ́n tààrà

[62] (Ó jẹ́) ìṣe Allāhu lórí àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú. O ò sì níí rí ìyípadà kan fún ìṣe Allāhu

[63] Àwọn ènìyàn ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo ni ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà. Àti pé kí l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí Àkókò náà ti súnmọ́!”

[64] Dájúdájú Allāhu ṣẹ́bi le àwọn aláìgbàgbọ́. Ó sì pèsè Iná t’ó ń jò fòfò sílẹ̀ dè wọ́n

[65] Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé; wọn kò níí rí olùṣọ́ tàbí alárànṣe kan

[66] Ní ọjọ́ tí A óò yí ojú wọn padà nínú Iná, wọn yó sì wí pé: “Yéè! Àwa ìbá tẹ̀lé ti Allāhu, àwa ìbá sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́.”

[67] Wọ́n wí pé: “Olúwa wa! Dájúdájú àwa tẹ̀lé àwọn aṣíwájú wa àti àwọn àgbààgbà wa. Wọ́n sì ṣì wá lọ́nà

[68] Olúwa wa! Fún wọn ní ìlọ́po méjì nínú ìyà. Kí O sì ṣẹ́bi lé wọn ní ìṣẹ́bi t’ó tóbi.”

[69] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó fi ìnira kan (Ànábì) Mūsā. Allāhu sì ṣàfọ̀mọ́ rẹ̀ nínú ohun tí wọ́n wí. Ó sì jẹ́ ẹni abiyì lọ́dọ̀ Allāhu

[70] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì sọ ọ̀rọ̀ òdodo

[71] (Allāhu) máa ṣàtúnṣe àwọn iṣẹ́ yín fun yín, Ó sì máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fun yín. Àti pé ẹni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ó kúkú ti jèrè ní èrèǹjẹ ńlá

[72] Dájúdájú Àwa fi iṣẹ́ láádá lọ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àpáta. Wọ́n kọ̀ láti gbé e; wọ́n páyà rẹ̀. Ènìyàn sì gbé e. Dájúdájú (ènìyàn) jẹ́ alábòsí, aláìmọ̀kan

[73] (Ènìyàn tẹ́rí gba ẹ̀sìn àṣegbaláádá) nítorí kí Allāhu lè fi ìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin, àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn ọ̀sẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin àti nítorí kí Allāhu lè gba ìronúpìwàdà fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

Ṣébà

Surah 34

[1] Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Àti pé tiRẹ̀ ni gbogbo ọpẹ́ ní ọ̀run. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán

[2] Ó mọ ohunkóhun t’ó ń wọnú ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó ń jáde látinú rẹ̀. (Ó mọ) ohunkóhun t’ó ń sọ̀kalẹ̀ látinú sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó ń gùnkè lọ sínú rẹ̀. Òun sì ni Àṣàkẹ́-ọ̀run, Aláforíjìn

[3] Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Àkókò náà kò níí dé bá wa.” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́. Èmi fi Olúwa mi búra. Dájúdájú ó máa dé ba yín (láti ọ̀dọ̀) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (Ẹni tí) òdiwọ̀n ọmọ iná-igún kò pamọ́ fún nínú sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. (Kò sí n̄ǹkan tí ó) kéré sí ìyẹn tàbí tí ó tóbi (jù ú lọ) àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú.”

[4] (Ó máa ṣẹlẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti èsè alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún

[5] Àti pé àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ burúkú nípa àwọn āyah Wa, (tí wọ́n lérò pé) àwọn mórí bọ́ nínú ìyà; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléró t’ó burú ń bẹ fún

[6] Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ rí i pé èyí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, òhun ni òdodo, àti pé ó ń ṣe ìtọ́sọ́nà sí ọ̀nà Alágbára, Ẹlẹ́yìn

[7] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ṣé kí á tọ́ka yín sí ọkùnrin kan tí ó máa fun yín ní ìró pé nígbà tí wọ́n bá fọn yín ká tán pátápátá (sínú erùpẹ̀), pé dájúdájú ẹ máa padà wà ní ẹ̀dá titun

[8] Ṣé ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni tàbí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀ ni?” Rárá o! Àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ti wà nínú ìyà àti ìṣìnà t’ó jìnnà

[9] Ṣé wọn kò rí ohun t’ó ń bẹ níwájú wọn àti ohun t’ó ń bẹ lẹ́yìn wọn ní sánmọ̀ àti ilẹ̀? Tí A bá fẹ́, Àwa ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, tàbí kí Á já apá kan sánmọ̀ lulẹ̀ lé wọn lórí mọ́lẹ̀. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo ẹrúsìn, olùronúpìwàdà

[10] Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Dāwūd ní oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Wa; Ẹ̀yin àpáta, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (A pe) àwọn ẹyẹ náà (pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.) A sì rọ irin fún un

[11] (A sọ fún un) pé ṣe àwọn ẹ̀wù irin t’ó máa bo ara, ṣe òrùka-ọrùn fún ẹ̀wù irin náà níwọ̀n-níwọ̀n. Kí ẹ sì ṣe rere. Dájúdájú Èmi ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[12] Àti pé (A tẹ) atẹ́gùn lórí bá fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, ìrìn oṣù kan ni ìrìn òwúrọ̀ rẹ̀, ìrìn oṣù kan sì ni ìrìn ìrọ̀lẹ́ rẹ̀ . A sì mú kí odò idẹ máa ṣàn nínú ilẹ̀ fún un. Ó sì wà nínú àwọn àlùjànnú, èyí t’ó ń ṣiṣẹ́ (fún un) níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀. Àti pé ẹni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi àṣẹ Wa nínú wọn, A máa fún un ní ìyà iná t’ó ń jò fòfò tọ́ wò

[13] Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí ó bá fẹ́ fún un nípa mímọ àwọn ilé t’ó dára, àwọn ère, àwo kòtò fífẹ̀ bí àbàtà àti àwọn ìkòkò t’ó rídìí múlẹ̀. Ẹ̀yin ènìyàn (Ànábì) Dāwūd, ẹ ṣiṣẹ́ ìdúpẹ́ (fún Allāhu). Díẹ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Mi sì ni olùdúpẹ́

[14] Nígbà tí A pàṣẹ pé kí ikú pa (Ànábì) Sulaemọ̄n, kò sí ohun tí ó mú àwọn àlùjànnú mọ̀ pé ó ti kú bí kò ṣe kòkòrò inú ilẹ̀ kan tí ó jẹ ọ̀pá rẹ̀. Nígbà tí ó wó lulẹ̀, ó hàn kedere sí àwọn àlùjànnú pé tí ó bá jẹ́ pé àwọn ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, àwọn ìbá tí wà nínú (iṣẹ́) ìyà t’ó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá

[15] Dájúdájú àmì kan wà fún àwọn Saba’ nínú ibùgbé wọn; (òhun ni) ọgbà oko méjì t’ó wà ní ọ̀tún àti ní òsì. “Ẹ jẹ nínú arísìkí Olúwa yín. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un.” Ìlú t’ó dára ni (ilẹ̀ Saba’. Allāhu sì ni) Olúwa Aláforíjìn

[16] Wọ́n gbúnrí (níbi ẹ̀sìn). Nítorí náà, A rán adágún odò tí wọ́n mọ odi yíká sí wọn. A sì pààrọ̀ oko wọn méjèèjì fún wọn pẹ̀lú oko méjì mìíràn tí ó jẹ́ oko eléso kíkorò, oko igi ẹlẹ́gùn-ún àti kiní kan díẹ̀ nínú igi sidir

[17] Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé wọ́n ṣàì moore. Ǹjẹ́ A máa san ẹnì kan lẹ́san ìyà bí kò ṣe aláìmoore

[18] A sì fi àwọn ìlú kan t’ó hàn sí ààrin ìlú tí A rán adágún odò sí àti àwọn ìlú tí A fi ìbùkún sí. A sì ṣètò ibùsọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n fún ìrìn-àjò ṣíṣe sínú àwọn ìlú náà. Ẹ rìn lọ sínú wọn ní òru àti ní ojú ọjọ́ pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀

[19] (Àwọn ará ìlú Saba’) wí pé: “Olúwa wa, mú àwọn ìrìn-àjò wa láti ìlú kan sí ìlú mìíràn jìnnà síra wọn.” Wọ́n ṣe àbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. A sì sọ wọ́n di ìtàn. A sì fọ́n wọn ká pátápátá. Dájúdájú àwọn àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́

[20] Dájúdájú ’Iblīs ti sọ àbá rẹ̀ di òdodo lé wọn lórí. Wọ́n sì tẹ̀lé e àfi igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[21] (’Iblīs) kò sì ní agbára kan lórí wọn bí kò ṣe pé kí A lè ṣàfi hàn ẹni t’ó gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ kúrò lára ẹni t’ó wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀. Olùṣọ́ sì ni Olúwa rẹ lórí gbogbo n̄ǹkan

[22] Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ pé (wọ́n jẹ́ olúwa) lẹ́yìn Allāhu.” Wọn kò ní ìkápá òdiwọ̀n ọmọ-iná igún nínú sánmọ̀ tàbí nínú ilẹ̀. Wọn kò sì ní ìpín kan nínú méjèèjì. Àti pé kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún Allāhu láààrin wọn

[23] Ìṣìpẹ̀ kò sì níí ṣàǹfààní lọ́dọ̀ Allāhu àfi fún ẹni tí Ó bá yọ̀ǹda fún. (Inúfu-àyàfu ní àwọn olùṣìpẹ̀ àti àwọn olùṣìpẹ̀-fún máa wà) títí A óò fi yọ ìjáyà kúrò nínú ọkàn wọn. Wọ́n sì máa sọ (fún àwọn mọlāika) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ (ní èsì ìṣìpẹ̀)?” Wọ́n máa sọ pé: “Òdodo l’Ó sọ (ìṣìpẹ̀ yin ti wọlé. Allāhu) Òun l’Ó ga, Ó tóbi

[24] Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Dájúdájú àwa tàbí ẹ̀yin wà nínú ìmọ̀nà tàbí nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[25] Sọ pé: “Wọn kò níí bi yín léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá; wọn kò sì níí bi àwa náà nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

[26] Sọ pé: “Olúwa wa yóò kó wa jọ papọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wa. Òun sì ni Onídàájọ́, Onímọ̀.”

[27] Sọ pé: “Ẹ fi hàn mí ná àwọn òrìṣà tí ẹ dàpọ̀ mọ́ Allāhu.” Rárá (kò ní akẹgbẹ́). Rárá sẹ́, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[28] A ò rán ọ níṣẹ́ àfi sí gbogbo ènìyàn pátápátá; (o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀

[29] Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

[30] Sọ pé: “Àdéhùn ọjọ́ kan ń bẹ fun yín, tí ẹ̀yin kò lè sún síwájú di ìgbà kan, ẹ ò sì lè fà á sẹ́yìn.”

[31] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “A ò níí ní ìgbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān yìí àti èyí t’ó wá ṣíwájú rẹ̀.” Tí ó bá jẹ́ pé o bá rí wọn ni nígbà tí wọ́n bá dá àwọn alábòsí dúró níwájú Olúwa wọn, (o máa rí wọn tí) apá kan wọn yóò dá ọ̀rọ̀ náà padà sí apá kan; àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ (nínú wọn) yóò wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga (nínú wọn) pé: “Tí kì í bá ṣe ẹ̀yin ni, àwa ìbá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”

[32] Àwọn t’ó ṣègbéraga yó sì wí fún àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ pé: “Ṣé àwa l’a ṣẹ yín lórí kúrò nínú ìmọ̀nà lẹ́yìn tí ó dé ba yín? Rárá o! Ọ̀daràn ni yín ni.”

[33] Àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ yó sì wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga pé: “Rárá! Ète òru àti ọ̀sán (láti ọ̀dọ̀ yín lókó bá wa) nígbà tí ẹ̀ ń pa wá ní àṣẹ pé kí á ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí á sì sọ (àwọn kan) di ẹgbẹ́ Rẹ̀.” Wọ́n fi àbámọ̀ wọn pamọ́ nígbà tí wọ́n rí ìyà. A sì kó ẹ̀wọ̀n sí ọrùn àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[34] Àti pé A ò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: “Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́.”

[35] Wọ́n tún wí pé: “Àwa ní dúkìá àti ọmọ jù (yín lọ); wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”

[36] Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀

[37] Kì í ṣe àwọn dúkìá yín, kì í sì ṣe àwọn ọmọ yín ni n̄ǹkan tí ó máa mu yín súnmọ́ Wa pẹ́kípẹ́kí àfi ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀san ìlọ́po wà fún nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Wọn yó sì wà nínú àwọn ipò gíga (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀

[38] Àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ aburú nípa àwọn āyah Wa, (tí wọ́n lérò pé) àwọn mórí bọ́ nínú ìyà; àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa mú wá sínú Iná.”

[39] Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ná, Òun l’Ó máa fi (òmíràn) rọ́pò rẹ̀. Ó sì l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.”

[40] Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà Ó máa sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ṣé ẹ̀yin ni wọ́n ń jọ́sìn fún?”

[41] Wọ́n á sọ pé: “Mímọ́ fún Ọ! Ìwọ ni Aláàbò wa, kì í ṣe àwọn. Rárá (wọn kò jọ́sìn fún wa). Àwọn àlùjànnú ni wọ́n ń jọ́sìn fún; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n gba àlùjànnú gbọ́

[42] Nítorí náà, ní òní apá kan yín kò ní ìkápá àǹfààní, kò sì ní ìkápá ìnira fún apá kan. A sì máa sọ fún àwọn t’ó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè nírọ́ wò.”

[43] Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, wọ́n á wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá yín ń jọ́sìn fún.” Wọ́n tún wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́.” Àti pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí nípa òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”

[44] A ò fún wọn ní àwọn tírà kan kan tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ nínú rẹ̀, A ò sì rán olùkìlọ̀ kan kan sí wọn ṣíwájú rẹ

[45] Àwọn t’ó ṣíwájú wọn náà pe òdodo nírọ́. (Ọwọ́ àwọn wọ̀nyí) kò sì tí ì tẹ ìdá kan ìdá mẹ́wàá nínú ohun tí A fún (àwọn t’ó ṣíwájú). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ Mi ní òpùrọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí

[46] Sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo ni mò ń ṣe wáàsí rẹ̀ fun yín pé, ẹ dúró nítorí ti Allāhu ní méjì àti ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú jinlẹ̀. Kò sí àlùjànnú kan lára ẹni yín. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ fun yín ṣíwájú ìyà líle kan.”

[47] Sọ pé: “Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan, ẹ̀yin lẹ kúkú lowó yín. Kò sí owó ọ̀yà mi (lọ́dọ̀ ẹnì kan) àfi lọ́dọ̀ Allāhu. Òun sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.”

[48] Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ l’Ó ń mú òdodo wá.”

[49] Sọ pé: “Òdodo ti dé. Irọ́ (èṣù) kò lè mú n̄ǹkan bẹ, kò sì lè dá n̄ǹkan padà (lẹ́yìn tó ti kú).”

[50] Sọ pé: “Tí mo bá ṣìnà, mo ṣìnà fún ẹ̀mí ara mi ni. Tí mo bá sì mọ̀nà, nípa ohun tí Olúwa mi fi ránṣẹ́ sì mi ní ìmísí ni. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Alásùn-únmọ́ ẹ̀dá.”

[51] Tí ó bá jẹ́ pé o lè rí (ẹ̀sín wọn ni) nígbà tí ẹ̀rù bá dé bá wọn (ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí i pé), kò níí sí ìmóríbọ́ kan (fún wọn). A sì máa gbá wọn mú láti àyè t’ó súnmọ́

[52] Wọn yóò wí pé: “A gbàgbọ́ nínú (al-Ƙur’ān báyìí).” Báwo ni ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ ìgbàgbọ́ òdodo láti àyè t’ó jìnnà (ìyẹn, ọ̀run).”

[53] Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ ṣíwájú (nílé ayé). Wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀kọ̀ láti àyè t’ó jìnnà (ìyẹn, ilé ayé)

[54] A sì fi gàgá sí ààrin àwọn àti ohun tí wọ́n ń ṣojú kòkòrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe fún àwọn ẹgbẹ́ wọn ní ìṣáájú. Dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn (nípa Ọjọ́ Àjíǹde)

Olùdásílẹ̀

Surah 35

[1] Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (Ẹni tí) Ó ṣe àwọn mọlāika alápá méjì àti mẹ́ta àti mẹ́rin ní Òjíṣẹ́. Ó ń ṣe àlékún ohun tí Ó bá fẹ́ lára ẹ̀dá. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[2] Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dá a dúró. Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[3] Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo

[4] Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan ní òpùrọ́ ṣíwájú rẹ. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí

[5] Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Kí ẹ sì má ṣe jẹ́ kí (Èṣù) ẹlẹ́tàn tàn yín jẹ

[6] Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá fun yín. Nítorí náà, ẹ mú un ní ọ̀tá. Ó kàn ń pe àwọn ìjọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè jẹ́ èrò inú Iná t’ó ń jò fòfò

[7] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi ń bẹ fún wọn

[8] Ṣé ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú ọwọ́ rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí ó sì ń rí i ní (iṣẹ́) dáadáa, (l’o fẹ́ banújẹ́ lé lórí?) Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí tiwọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe

[9] Allāhu ni Ẹni tí Ó fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tu ẹ̀ṣújò sókè. A sì fi fún ìlú (tí ilẹ̀ rẹ̀) ti kú lómi mu. A sì fi ta ilẹ̀ náà jí lẹ́yìn tí ó ti kú. Báyẹn ni àjíǹde (ẹ̀dá yó ṣe rí)

[10] Ẹní tí ó bá ń fẹ́ iyì dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo iyì pátápátá. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ dáadáa ń gòkè lọ. Ó sì ń gbé iṣẹ́ rere gòkè (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Àwọn tí wọ́n ń pète àwọn aburú, ìyà líle ń bẹ fún wọn. Ète àwọn wọ̀nyẹn sì máa parun

[11] Allāhu da yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ó tún da yín) láti ara àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe yín ní akọ-abo. Obìnrin kan kò níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àti pé A ò níí fa ẹ̀mí ẹlẹ́mìí-gígùn gùn, A ò sì ní ṣe àdínkù nínú ọjọ́ orí (ẹlòmíìràn), àfi kí ó ti wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu

[12] Àwọn odò méjì náà kò dọ́gba; èyí ni (omi) dídùn gan-an, tí mímu rẹ̀ ń lọ tìnrín lọ́fun. Èyí sì ni (omi) iyọ̀ t’ó móró. Àti pé nínú gbogbo (omi odò wọ̀nyí) l’ẹ ti ń jẹ ẹran (ẹja) tútù. Ẹ sì ń wa kùsà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ẹ̀ ń wọ̀ (sára). O sì ń rí àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń la ààrin omi kọjá nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Allāhu àti nítorí ki ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)

[13] (Allāhu) ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Àwọn tí ẹ sì ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá kan lórí èpo kóró inú dàbínù

[14] Tí ẹ bá pè wọ́n, wọn kò lè gbọ́ ìpè yín. Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n gbọ́, wọn kò lè da yín lóhùn. Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò tako bí ẹ ṣe fi wọ́n ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Kò sì sí ẹni tí ó lè fún ọ ní ìró kan (nípa ẹ̀dá ju) irú (ìró tí) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (fún ọ nípa wọn)

[15] Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ni aláìní (tí ẹ ní bùkátà) sí Allāhu. Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́

[16] Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò nílẹ̀. Ó sì máa mú ẹ̀dá titun wá

[17] Ìyẹn kò sì kágara kan bá Allāhu

[18] Ẹlẹ́rù ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Kódà kí ẹnì kan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn ké sí (ẹlòmíìràn) fún àbárù ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọn kò níí bá a ru kiní kan nínú rẹ̀, ìbáà jẹ́ ìbátan. Àwọn tí ò ń ṣèkìlọ̀ fún ni àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń kírun. Ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ó ṣàfọ̀mọ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[19] Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba

[20] Àwọn òòkùn àti ìmọ́lẹ̀ (kò dọ́gba)

[21] Àwọn ibòji àti ìgbóná òòrùn (kò dọ́gba)

[22] Àwọn alààyè àti òkú kò dọ́gba. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀rọ̀ gbọ́. Ìwọ kò sì lè fún ẹni tí ó wà nínú sàréè ní ọ̀rọ̀ gbọ́

[23] Ìwọ kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀

[24] Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Kò sí ìjọ kan (ṣíwájú rẹ) àfi kí olùkìlọ̀ ti rè kọjá láààrin wọn

[25] Tí wọ́n bá sì ń pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn t’ó ṣíwájú wọn náà kúkú pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) nírọ́ (nígbà tí) àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, àwọn ìpín-ìpín Tírà àti Tírà t’ó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn

[26] Lẹ́yìn náà, Mo gbá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí

[27] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀? A sì fi mú àwọn èso tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn jáde. Àti pé àwọn ojú ọ̀nà funfun àti pupa tí àwọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn pẹ̀lú aláwọ̀ dúdú kirikiri wà nínú àwọn àpáta

[28] Àti pé ó wà nínú àwọn ènìyàn, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti àwọn ẹran-ọ̀sìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn, gẹ́gẹ́ bí (àwọ̀ èso àti àpáta) wọ̀nyẹn (ṣe yàtọ̀ síra wọn). Àwọn t’ó ń páyà Allāhu nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni àwọn onímọ̀ (tí wọ́n mọ̀ pé), dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Aláforíjìn

[29] Dájúdájú àwọn t’ó ń ké tírà Allāhu, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń ná nínú n̄ǹkan tí A ṣe ní arísìkí fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, wọ́n ń nírètí sí òwò kan tí kò níí parun

[30] (Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́

[31] Ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà, òhun ni òdodo tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀

[32] Lẹ́yìn náà, A jogún tírà (al-Ƙur’ān) fún àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Nítorí náà, alábòsí t’ó ń bo ẹ̀mí ara rẹ̀ sí wà nínú wọn. Olùṣe-déédé wà nínú wọn. Olùgbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere tún wà nínú wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ìyẹn sì ni oore àjùlọ t’ó tóbi

[33] Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọn yóò wọ inú rẹ̀. Àwọn kerewú wúrà àti òkúta olówó iyebíye ni A óò máa fi ṣe ọ̀ṣọ́ fún wọn nínú rẹ̀. Àti pé aṣọ àláárì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀

[34] Wọ́n yóò sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú ìbànújẹ́ kúrò fún wa. Dájúdájú Olúwa wa ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́

[35] Ẹni tí Ó sọ̀ wá kalẹ̀ sínú ibùgbé gbére nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Wàhálà kan kò níí kàn wá nínú rẹ̀. Ìkáàárẹ̀ kan kò sì níí bá wa nínú rẹ̀

[36] Àti pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, iná Jahnamọ ń bẹ fún wọn. A ò níí pa wọ́n (sínú rẹ̀), áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò kú. A ò sì níí gbé ìyà rẹ̀ fúyẹ́ fún wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ ní ẹ̀san

[37] Wọn yóò máa lọgun ìrànlọ́wọ́ nínú rẹ̀ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde nítorí kí á lè lọ́ ṣe iṣẹ́ rere, yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe.” Ṣé A ò fun yín ní ẹ̀mí gígùn lò tó fún ẹni tí ọ́ bá fẹ́ lo ìṣítí láti rí i lò nínú àsìkò náà ni? Olùkìlọ̀ sì wá ba yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí

[38] Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[39] Òun ní Ẹni t’Ó ń fi yín ṣe àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan lọ́dọ̀ Olúwa wọn bí kò ṣe ìbínú. Àìgbàgbọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì níí fún wọn ní àlékún kan bí kò ṣe òfò

[40] Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn òrìṣà yín tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹ fi ohun tí wọ́n dá hàn mí lórí ilẹ̀? Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) níbi (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Tàbí A fún wọn ní tírà kan, tí wọ́n ní ẹ̀rí t’ó yanjú nínú rẹ̀? Rárá o! Kò sí àdéhùn kan tí àwọn alábòsí, apá kan wọn ń ṣe fún apá kan bí kò ṣe ẹ̀tàn.”

[41] Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró ṣinṣin tí wọn kò fi yẹ̀ lulẹ̀. Dájúdájú tí wọ́n bá sì yẹ̀ lulẹ̀, kò sí ẹnì kan kan tí ó máa mú un dúró lẹ́yìn Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn

[42] Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé: "Dájúdájú tí olùkìlọ̀ kan bá fi lè wá bá àwọn, dájúdájú àwọn yóò mọ̀nà tààrà ju èyíkéyìí nínú ìjọ (t’ó ti ṣíwájú) lọ." Nígbà tí olùkìlọ̀ sì wá bá wọn, (èyí) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún òdodo)

[43] ní ti ṣíṣe ìgbéraga lórí ilẹ̀ àti ní ti ìpète aburú. Ìyà ìpète aburú kò sì níí kò lé ẹnì kan lórí àfi oníṣẹ́ aburú. Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe ìṣe (Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́? Nítorí náà, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu. Àní sẹ́, o ò níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu

[44] Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n sì ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) lọ! Àti pé kò sí kiní kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tí ó lè mórí bọ́ lọ́wọ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alágbára

[45] Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu yó (tètè) máa mú ènìyàn pẹ̀lú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ni, ìbá tí ṣẹ́ ku n̄ǹkan ẹlẹ́mìí kan kan mọ́ lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń lọ́ wọn lára di gbèdéke àkókò kan. Nígbà tí àkókò náà bá dé, dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀

Yāsĩ

Surah 36

[1] Yā sīn

[2] (Allāhu) búra pẹ̀lú Al-Ƙur’ān tírà ọgbọ́n

[3] Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́

[4] wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām)

[5] (Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí t’ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[6] nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà)

[7] Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́

[8] Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn. Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè

[9] Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran

[10] Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o ò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́

[11] Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìṣítí (al-Ƙur’ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé

[12] Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan t’ó yanjú

[13] Fi àpèjúwe kan lélẹ̀ fún wọn nípa àwọn ará ìlú kan nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wá bá wọn

[14] (Rántí) nígbà tí A rán Òjíṣẹ́ méjì níṣẹ́ sí wọn. Wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. A sì fi ẹnì kẹta ró àwọn méjèèjì lágbára. Wọ́n sì sọ pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.”

[15] Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú tiwa. Àjọkẹ́-ayé kò sì sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.”

[16] Wọ́n sọ pé: "Olúwa wa mọ̀ pé dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín

[17] Kò sì sí ojúṣe kan fún wa bí kọ̀ ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé.”

[18] Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa rí àmì aburú lára yín. Tí ẹ ò bá jáwọ́ (níbi ìpèpè yín), dájúdájú a máa sọ yín lókò pa. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì jẹ yín láti ọ̀dọ̀ wa.”

[19] Wọ́n sọ pé: "Àmì aburú yín ń bẹ pẹ̀lú yín. Ṣé nítorí pé wọ́n ṣe ìṣítí fun yín (l’ẹ fi rí àmì aburú lára wa)? Kò rí bẹ́ẹ̀! Ìjọ alákọyọ ni yín ni

[20] Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́ náà

[21] Ẹ tẹ̀lé ẹni tí kò bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín. Olùmọ̀nà sì ni wọ́n

[22] Kí ni ó máa mú mi tí èmi kò fi níí jọ́sìn fún Ẹni tí Ó pilẹ̀ ẹ̀dá mi? Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí

[23] Ṣé kí n̄g sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́ fi ìnira kàn mí, ìṣìpẹ̀ wọn kò lè rọ̀ mí lọ́rọ̀ kiní kan, wọn kò sì lè gbà mí là

[24] (Bí èmi kò bá jọ́sìn fún Allāhu) nígbà náà dájúdájú mo ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[25] Dájúdájú èmi gbàgbọ́ nínú Olúwa Ẹlẹ́dàá yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́ mi.”

[26] Wọ́n sọ pé: “Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn mi ìbá ní ìmọ̀

[27] nípa bí Olúwa mi ṣe foríjìn mí àti (bí) Ó ṣe fi mí sí ara àwọn alápọ̀n-ọ́nlé (wọn ìbá ronú pìwàdà).”

[28] A kò sọ ọmọ ogun kan kalẹ̀ lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí láti sánmọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. A ò sì sọ (mọlāika kan) kalẹ̀ (fún ìparun wọn)

[29] (Ìparun wọn) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan; nígbà náà ni wọ́n di òkú kalẹ̀

[30] Àbámọ̀ mà ni fún àwọn ẹrúsìn náà; òjíṣẹ́ kan kò níí wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́

[31] Ṣé wọn kò rí i pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? (Ṣé wọn kò rí i pé) dájúdájú wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ wọn mọ́ (nílé ayé) ni

[32] Dájúdájú gbogbo wọn pátápátá sì ni wọ́n máa kó wá sí ọ̀dọ̀ Wa

[33] Àmì ni òkú ilẹ̀ jẹ́ fún wọn. A sọ ọ́ di àyè. A sì mú èso jáde láti inú rẹ̀. Wọ́n sì ń jẹ nínú rẹ̀

[34] A tún ṣe àwọn ọgbà dàbínù àti àjàrà sínú ilẹ̀. A sì mú àwọn odò ìṣẹ́lẹ̀rú ṣẹ́ yọ láti inú rẹ̀

[35] nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe! Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni? “nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ kì í sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?” Ìtúmọ̀ kejì dúró lé iṣẹ́ Allāhu lórí ìṣẹ̀dá n̄ǹkan oko. Ìyẹn ni pé

[36] Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀. tàbí ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ kan tàbí ìmọ̀ ìròrí kan tàbí èyíkéyìí ìmọ̀ kan lòdì sí āyah kan nínú al-Ƙur’ān tàbí hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé. “zaoj” ni ẹyọ. “Zaoj” sì ń túmọ̀ sí akọ tàbí abo nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ènìyàn tàbí ọmọ bíbí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Najm; 53:45 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:39. àmọ́ tí ìkíní kejì yàtọ̀ síra wọn ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí akọ àti abo n̄ǹkan dídùn àti n̄ǹkan kíkorò a lè rí èso mímu tàbí èso jíjẹ kan tí ó máa jẹ́ oríṣiríṣi. Ìtúmọ̀ olóríṣiríṣi tún lọ lábẹ́ āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Nítorí náà zaoj kò pọn dandan kí ó ní ìtúmọ̀ akọ àti abo nìkan. Oríṣiríṣi ni “zaoj”; akọ jẹ oríṣi kan

[37] Òru jẹ́ àmì kan fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn). ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìparan súná ọmọ náà. Báwo ni a ó ṣe ka ọjọ́ méje náà? Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn kan lérò pé kódà kí ọjọ́ ìbímọ ku ìṣẹ́jú kan tí a ó fi bọ́ sínú ọjọ́ titun. Bí àpẹẹrẹ tí obìnrin kan bá bímọ ní ọ̀sán Alaadi

[38] Àti pé òòrùn yóò máa rìn lọ sí àyè rẹ̀. Ìyẹn ni ètò (ti) Alágbára, Onímọ̀

[39] Òṣùpá náà, A ti ṣe òdíwọ̀n àwọn ibùsọ̀ fún un (tí ó ti ma máa tóbi sí i) títí ó máa fi padà dà bíi ọ̀gọ́mọ̀ ọ̀pẹ t’ó ti pẹ́

[40] Kò yẹ fún òòrùn láti lo àsìkò òṣùpá. Kò sì yẹ fún alẹ́ láti lo àsìkò ọ̀sán. Ìkọ̀ọ̀kan wà ní òpópónà róbótó t’ó ń tọ̀

[41] Ó tún jẹ́ àmì fún wọn pé dájúdájú Àwa gbé àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn gun ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́

[42] A tún ṣẹ̀dá (òmíràn) fún wọn nínú irú rẹ̀ tí wọn yóò máa gún

[43] Tí A bá fẹ́ Àwa ìbá tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Kò níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn. Wọn kò sì níí gbà wọ́n là

[44] Àfi (kí Á fi) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa (yọ wọ́n jáde, kí A sì tún fún wọn ní) ìgbádùn ayé títí di ìgbà díẹ̀

[45] (Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: "Ẹ ṣọ́ra fún ohun t’ó wà níwájú yín àti ohun t’ó wà lẹ́yìn yín nítorí kí A lè kẹ yín

[46] Àti pé āyah kan nínú àwọn āyah Olúwa wọn kò níí wá bá wọn àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀

[47] Nígbà tí A bá sì sọ fún wọn pé: "Ẹ ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fun yín.", àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Ṣé kí á bọ́ ẹni tí (ó jẹ́ pé) Allāhu ìbá fẹ́ ìbá bọ́ ọ (àmọ́ kò bọ́ ọ. Àwa náà kò sì níí bá A bọ́ ọ)?” Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé (ẹ wà) nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[48] Wọ́n sì ń wí pé: "Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[49] Wọn kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa gbá wọn mú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àríyànjiyàn lọ́wọ́

[50] Nígbà náà, wọn kò níí lè sọ àsọọ́lẹ̀ kan. Wọn kò sì níí lè padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn

[51] Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn

[52] Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?" Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀)

[53] Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Wa

[54] Nítorí náà, ní òní wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò sì níí san yín ní ẹ̀san àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[55] Dájúdájú ní òní àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò kún fún ìgbádùn

[56] Àwọn àti àwọn ìyàwó wọn yóò wà lábẹ́ àwọn ibòji, wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn

[57] Èso wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ohun tí wọ́n yóò máa bèèrè fún tún wà fún wọn pẹ̀lú

[58] Àlàáfíà ni ọ̀rọ̀ tí ó máa wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[59] Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ bọ́ sí ọ̀tọ̀ ní òní

[60] Ẹ̀yin ọmọ (Ànábì) Ādam, ṣe Èmi kò ti pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ má ṣe jọ́sìn fún Èṣù? Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín

[61] Àti pé kí ẹ jọ́sìn fún Mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà

[62] Àti pé (Èṣù) kúkú ti ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀dá lọ́nà nínú yín. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni

[63] Èyí ni iná Jahanamọ tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín

[64] Ẹ wọ inú rẹ̀ ní òní nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́

[65] Ní òní, A máa di ẹnu wọn pa. Àwọn ọwọ́ wọn yó sì máa bá Wa sọ̀rọ̀. Àwọn ẹsẹ̀ wọn yó sì máa jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[66] Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fọ́ wọn lójú, wọn ìbá sì yára wá sójú ọ̀nà, báwo ni wọ́n ṣe máa ríran ná

[67] Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá yí wọn padà sí ẹ̀dá mìíràn nínú ibùgbé wọn. Wọn kò sì níí lágbára láti lọ síwájú. Wọn kò sì níí padà sẹ́yìn

[68] Ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ẹ̀mí gígùn lò, A óò sọ ẹ̀dá rẹ̀ di ọ̀lẹ, ṣé wọn kò níí ṣe làákàyè ni

[69] A ò kọ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ewì. Kò sì rọ̀ ọ́ lọ́rùn (láti kéwì). Kí ni ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí i) bí kò ṣe ìrántí àti al-Ƙur’ān pọ́nńbélé

[70] nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ alààyè àti nítorí kí ọ̀rọ̀ náà lè kò lórí àwọn aláìgbàgbọ́

[71] Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá nínú ohun tí A fi ọwọ́ Wa ṣe (tí ó jẹ́) àwọn ẹran-ọ̀sìn fún wọn? Wọ́n sì ní ìkápá lórí wọn

[72] A tẹ̀ wọ́n lórí ba fún wọn; wọ́n ń gùn nínú wọn, wọ́n sì ń jẹ nínú wọn

[73] Àwọn àǹfààní àti ohun mímu tún wà fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni

[74] Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣàrànṣe fún wọn

[75] Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún wọn; ṣebí àwọn òrìṣà ni ọmọ ogun tí A máa kó wọ inú Iná fún àwọn abọ̀rìṣà (láti fi jẹ wọ́n níyà)

[76] Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú Àwa mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀

[77] Ṣé ènìyàn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú àtọ̀? (Ṣebí lẹ́yìn) ìgbà náà l’ó di alátakò pọ́nńbélé

[78] Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa. Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: "Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun

[79] Sọ pé: "Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá

[80] (Òun ni) Ẹni tí Ó mú iná jáde fun yín láti ara igi tútù. Ẹ sì ń fi ko iná

[81] Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò ní agbára láti dá irú wọn (mìíràn) bí? Rárá (Ó ní agbára). Òun sì ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀

[82] Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀

[83] Nítorí náà, mímọ́ ni fún Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí

Àwọn tó ń tò lẹ́sẹẹsẹ

Surah 37

[1] (Allāhu búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika olùtò-lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tààrà

[2] àti àwọn mọlāika t’ó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà

[3] àti àwọn mọlāika òǹké-tírà ìrántí

[4] Dájúdájú Ọlọ́hun yín, Ọ̀kan ṣoṣo ni

[5] Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn

[6] Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́

[7] àti ìṣọ́ níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun

[8] (Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika t’ó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀). (Àwọn mọlāika) yó sì máa ku (àwọn èṣù) lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀)

[9] Wọ́n ń lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn

[10] (Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní kíkún) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná t’ó máa jó o tẹ̀lé e

[11] Bi wọ́n léèrè wò pé ṣé àwọn ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (ènìyàn) tí A dá? Dájúdájú Àwa dá wọn láti ara erùpẹ̀ t’ó lẹ̀ mọ́ra wọn

[12] Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́

[13] Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí

[14] Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́

[15] Wọ́n sì wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé

[16] Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni

[17] Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́

[18] Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ

[19] Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn

[20] Wọ́n á wí pé: "Ègbé wa! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san

[21] Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè nírọ́

[22] Ẹ kó àwọn t’ó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún

[23] lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm

[24] Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè

[25] Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ranra yín lọ́wọ́

[26] Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni

[27] Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè

[28] (Àwọn ènìyàn) wí pé: "Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà)

[29] (Àwọn àlùjànnú) wí pé: "Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[30] Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu àlà

[31] Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò

[32] Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà

[33] Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà

[34] Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

[35] Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé "Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu.", wọn yóò máa ṣègbéraga

[36] Wọ́n sì ń wí pé: "Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan

[37] Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà

[38] Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò

[39] A ò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[40] Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà

[41] Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀

[42] àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé

[43] nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

[44] Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn

[45] Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ káà kiri ọ̀dọ̀ wọn

[46] Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn t’ó máa mu ún

[47] Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀

[48] Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn

[49] Wọ́n dà bí tinú ẹyin. ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run

[50] Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè

[51] Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan

[52] tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde

[53] Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”

[54] Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)

[55] Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm

[56] Ó (sì) sọ pé: "Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán

[57] Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná

[58] Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí

[59] Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà

[60] Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá

[61] Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ

[62] Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)

[63] Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí

[64] Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm

[65] Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù

[66] Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, wọn yóò fi kún inú wọn bámúbámú

[67] Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu n̄ǹkan mímu àwọyúnwẹ̀jẹ̀ gbígbóná lé e lórí

[68] Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm

[69] Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà

[70] Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn

[71] Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn

[72] Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn

[73] Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí

[74] Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà

[75] Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè

[76] A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá

[77] A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀

[78] A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn

[79] Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá

[80] Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)

[81] Dájúdájú òun wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[82] Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami

[83] Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀

[84] (Ẹ rántí) nígbà tí òun náà dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́

[85] (Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún

[86] Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu

[87] Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”

[88] Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ gan-an

[89] Ó sì sọ pé: "Dájúdájú ó rẹ̀ mí

[90] Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ

[91] Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni

[92] Kí ni ó ṣe yín tí ẹ ò sọ̀rọ̀

[93] Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú)

[94] (Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́

[95] Ó sọ pé: "Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni

[96] Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[97] Wọ́n wí pé: "Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná

[98] Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ

[99] Ó sọ pé: "Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀)

[100] Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere

[101] A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin aláfaradà

[102] Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: "Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́

[103] Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀

[104] A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm

[105] o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)

[106] Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé

[107] A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀

[108] A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn

[109] Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm

[110] Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)

[111] Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[112] A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere

[113] Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (t’ó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì

[114] Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn

[115] A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá

[116] A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn)

[117] A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà t’ó yanjú

[118] A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà

[119] A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn

[120] Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn

[121] Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)

[122] Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[123] Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́

[124] (Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni

[125] Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Òun l’Ó sì dára jùlọ nínú àwọn olùdájọ́. (sūrah al-’A‘rọ̄f 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Òun sì yára jùlọ nínú àwọn oníṣirò. (sūrah al-’Ani‘ām 6:62) olùdájọ́ aláàánú ìbáà mọ bíi ọmọ iná igún àfi kí Allāhu jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Kódà àdámọ́ owó àti okòwò tí wọ́n sọ di “ọrọ̀-Ajé. Àwọn t’ó ń bọ́ ẹlòmíìràn náà ń sọra wọn di olùpèsè. Yàtọ̀ sí pé Allāhu ti fi rinlẹ̀ pé Òun nìkan ni Olùpèsè fún gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Tí èyí kò bá tí ì dá àwọn kan lójú bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ gbé gbogbo ìpèsè olúkùlùkù lórí ìwọ̀n nínú àánú tí Allāhu fi sí àwọn ẹ̀dá kan lọ́kàn ni wọ́n fi di aláàánú. Nítorí náà Allāhu ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú

[126] (ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́

[127] Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná

[128] Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà

[129] A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn

[130] Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās

[131] Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)

[132] Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[133] Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́

[134] (Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là

[135] Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́)

[136] Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run

[137] Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀

[138] àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni

[139] Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́

[140] (Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́

[141] Ó sì bá wọn muje pọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí aje ṣí mọ́ lórí

[142] Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi

[143] Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu

[144] dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde

[145] Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera

[146] A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó

[147] A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i

[148] Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀

[149] Bi wọ́n léèrè wò pé: "Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin

[150] Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí

[151] Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé

[152] Allāhu bímọ." Dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n

[153] Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni

[154] Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí

[155] Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni

[156] Tàbí ẹ ní ẹ̀rí t’ó yanjú lọ́wọ́ ni

[157] Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[158] Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni

[159] Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)

[160] Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà

[161] Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu)

[162] ẹ ò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà

[163] àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm

[164] Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀

[165] Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

[166] Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu)

[167] Wọ́n kúkú ń wí pé

[168] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́

[169] dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn ẹni ẹ̀ṣà

[170] Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀

[171] Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́

[172] Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún

[173] Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí

[174] Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀

[175] Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò

[176] Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú

[177] Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí agboolé wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún

[178] Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná

[179] Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò

[180] Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀)

[181] Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́

[182] Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

Ṣọ̄d

Surah 38

[1] Sọ̄d. (Allāhu búra pẹ̀lú) al-Ƙur’ān, tírà ìrántí

[2] Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wà nínú ìgbéraga àti ìyapa (òdodo)

[3] Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n kígbe tòò nígbà tí kò sí ibùsásí kan

[4] Wọ́n ṣèèmọ̀ pé olùkìlọ̀ kan nínú wọn wá bá wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: "Èyí ni òpìdán, òpùrọ́

[5] Ṣé ó máa sọ àwọn òrìṣà di Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí A óò máa jọ́sìn fún ni? Dájúdájú èyí mà ni n̄ǹkan ìyanu

[6] Àwọn aṣíwájú nínú wọn sì lọ (káàkiri láti wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn wọn) pé: "Ẹ máa bá (ìbọ̀rìṣà) lọ, kí ẹ sì dúró ṣinṣin ti àwọn òrìṣà yín. Dájúdájú èyí (jíjẹ́ ọ̀kan ṣoṣo Allāhu) ni n̄ǹkan tí wọ́n ń gbà lérò (láti fi pa àwọn òrìṣà yín run)

[7] Àwa kò gbọ́ èyí nínú ẹ̀sìn ìkẹ́yìn (ìyẹn, ẹ̀sìn kristiẹniti) . Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àdápa irọ́

[8] Ṣé Wọ́n sọ Ìrántí kalẹ̀ fún un láààrin wa ni?" Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa Ìrántí Mi (tí Mo sọ̀kalẹ̀ ni). Rárá, wọn kò tí ì tọ́ ìyà Mi wò ni

[9] Tàbí (ṣé) àwọn ni wọ́n ni àwọn àpótí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ, Alágbára, Ọlọ́rẹ

[10] Tàbí tiwọn ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin méjèèjì? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wọn wá àwọn ọ̀nà láti fi gùnkè wá (bá Wa)

[11] A máa ṣẹ́gun ọmọ ogun t’ó wà níbẹ̀ yẹn nínú ọmọ ogun oníjọ

[12] Àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti Fir‘aon, eléèkàn, wọ́n pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn

[13] Ìjọ Thamūd, ìjọ Lūt àti àwọn ará ’Aekah, àwọn wọ̀nyẹn (tún ni) àwọn ìjọ (t’ó pe òdodo nírọ́)

[14] Kò sí ẹnì kan nínú wọn tí kò pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà Mi sì kò lé wọn lórí

[15] Àwọn wọ̀nyí kò retí kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan, tí kò níí sí ìdápadà (tàbí ìdádúró) kan fún un (t’ó bá dé)

[16] Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, yára fi ìwé iṣẹ́ wa (àti ẹ̀san wa) lé wa lọ́wọ́ ṣíwájú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́

[17] Ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ. Kí o sì ṣèrántí ìtàn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) Dāwūd, alágbára. Dájúdájú ó jẹ́ olùronúpìwàdà

[18] Dájúdájú Àwa tẹ àwọn àpáta lórí ba tí wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ (fún Allāhu) ní àṣálẹ́ àti nígbà tí òòrùn bá yọ

[19] Àti àwọn ẹyẹ náà, A kó wọn jọ fún un. Ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ (láti ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu)

[20] Àti pé A fún ìjọba rẹ̀ ní agbára. A sì fún un ní ipò Ànábì àti ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ àti ìdájọ́

[21] Ǹjẹ́ ìró àwọn oníjà ti dé ọ̀dọ̀ rẹ; nígbà tí wọ́n pọ́n ògiri ilé ìjọ́sìn

[22] Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Dāwūd, ẹ̀rù bà á láti ara wọn. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Oníjà méjì (ni wá). Apá kan wa tayọ ẹnu-àlà sí apá kan. Nítorí náà, dájọ́ láààrin wa pẹ̀lú òdodo. Má ṣàbòsí. Kí o sì tọ́ wa sí ọ̀nà tààrà

[23] Dájúdájú èyí ni arákùnrin mi. Ó ní abo ewúrẹ́ mọ́kàndín-lọ́gọ́rùn-ún. Èmi sì ní abo ewúrẹ́ ẹyọ kan. Ó sì sọ pé: "Fà á lé mi lọ́wọ́. Ó sì borí mi nínú ọ̀rọ̀

[24] (Ànábì Dāwūd) sọ pé: "Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-àlà lórí apá kan àfi àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n. (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni- afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu). òǹkà ìyàwó wọn lè pọ̀ ní òǹkà kì í ṣe ní ti ìgbádùn adùn-ara bí kò ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ kọ́ Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ẹ̀kọ́ ìgbẹ́jọ́ nítorí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ fi ṣe adájọ́ láààrin àwọn ìjọ rẹ̀. Àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn ni àṣíṣe t’ó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Dāwūd ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Èyí náà sì ni ohun tí ó tọrọ àforíjìn Ọlọ́hun fún

[25] Nítorí náà, A ṣàforíjìn ìyẹn fún un. Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un lọ́dọ̀ Wa

[26] (Ànábì) Dāwūd, dájúdájú Àwa ṣe ọ́ ní àrólé lórí ilẹ̀. Nítorí náà, dájọ́ láààrin àwọn ènìyà́n pẹ̀lú òdodo. Má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú nítorí kí ó má baà ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Dájúdájú àwọn t’ó ń sọnù kúrò nínú ẹ̀sìn Allāhu, ìyà líle wà fún wọn nítorí pé wọ́n gbàgbé Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́

[27] A kò ṣẹ̀dá sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì pẹ̀lú irọ́. (Irọ́), ìyẹn ni èrò àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Iná

[28] Ṣé kí Á ṣe àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere bí (A ó ti ṣe) àwọn òbìlẹ̀jẹ́ lórí ilẹ̀? Tàbí ṣé kí Á ṣe àwọn olùbẹ̀rù (Mi bí A ó ti ṣe) àwọn aṣebi

[29] (Èyí ni) Tírà ìbùkún tí A sọ̀ kalẹ̀ fún ọ nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa àwọn āyah rẹ̀ àti nítorí kí àwọn onílàákàyè lè lo ìrántí

[30] A fi (Ànábì) Sulaemọ̄n ta (Ànábì) Dāwūd lọ́rẹ. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sọ́dọ̀ (Allāhu) ni (nípa ìronúpìwàdà)

[31] (Rántí) nígbà tí wọ́n kó àwọn ẹṣin akáwọ́ọ̀jà-lérí asárétete wá bá a ní ìrọ̀lẹ́

[32] ó sọ pé: "Dájúdájú èmi fẹ́ràn ìfẹ́ ohun rere (ìyẹn, àwọn ẹṣin náà) dípò ìrántí Olúwa Mi (ìyẹn, ìrun ‘Asr) títí òòrùn fi wọ̀

[33] Ẹ dá wọn padà sọ́dọ̀ mi. "Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi idà gé wọn ní ẹsẹ̀ àti ní ọrùn

[34] Dájúdájú A dán (Ànábì) Sulaemọ̄n wò. A ju abara kan sórí àga rẹ̀. Lẹ́yìn náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) ṣẹ́rí padà (pẹ̀lú ìronúpìwàdà). Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní ìyàwó t’ó tó ọgọ́rùn-ún lábẹ́ òfin ẹ̀tọ́ (ìyẹn ni pé Allāhu s.w.t. l’Ó ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún un). Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sì fi Allāhu búra ní ọjọ́ kan pé kì í ṣe ara òrùka Ànábì Sulaemọ̄n ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni àwọ̀ Ànábì Sulaemọ̄n wà. Báwo wá ni ó ṣe máa jẹ́ pé nípasẹ̀ òrùka Ànábì Sulaemọ̄n ni àwọ̀ rẹ̀ fi máa kúrò lára rẹ̀ sí ara èṣù àlùjànnú nígbà tí Ànábì Sulaemọ̄n kì í ṣe òpìdán? Ànábì Sulaemọ̄n kò sì fi òrùka jọba áḿbọ̀sìbọ́sí pé nígbà tí kò bá sí òrùka rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ l’ó máa fún ẹlòmíìràn ní àyè láti di ọba! Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:102. W-Allāhu ’a‘lam

[35] Ó sọ pé: "Olúwa mi, forí jìn mí. Kí O sì ta mí ní ọrẹ ìjọba kan èyí tí kò níí tọ́ sí ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn mi. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Ọlọ́rẹ

[36] Nítorí náà, A tẹ atẹ́gùn ba fún un. Ó ń fẹ́ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn síbi tí ó bá fẹ́

[37] Àti àwọn èṣù àlùjànnú; gbogbo àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn awakùsà (ni A tẹ̀ ba fún un)

[38] Àti àwọn (àlùjànnú) mìíràn tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mọ́lẹ̀ (A tẹ̀ wọ́n ba fún un)

[39] Èyí ni ọrẹ Wa. Nítorí náà, fi tọrẹ tàbí kí ó mú un dání láì la ìṣírò lọ (lọ́run)

[40] Dájúdájú ìsúnmọ́ (Wa) àti àbọ̀ rere sì wà fún un ní ọ̀dọ̀ Wa

[41] Ṣèrántí ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ayyūb. Nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ (pé): "Dájúdájú Èṣù ti kó ìnira (àìsàn) àti ìyà bá mi

[42] (Mọlāika sọ fún un pé): "Fi ẹsẹ̀ rẹ janlẹ̀. Èyí ni omi ìwẹ̀ tútù àti omi mímu (fún ìwòsàn rẹ)

[43] A sì ta á lọ́rẹ àwọn ará ilé rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn. (Ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè

[44] Fi ọwọ́ rẹ mú ìdì igi koríko tútù kí o fi lu (ìyàwó) rẹ. Má ṣe yapa ìbúra rẹ. Dájúdájú Àwa rí (’Ayyūb) ní onísùúrù. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni (nípa ìronúpìwàdà)

[45] Ṣèrántí àwọn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb; àwọn alágbára, olùríran (nípa ẹ̀sìn)

[46] Dájúdájú Àwa ṣà wọ́n lẹ́ṣà pẹ̀lú ẹ̀ṣà kan; ìrántí Ilé Ìkẹ́yìn

[47] Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni ẹ̀ṣà, ẹni rere jùlọ ní ọ̀dọ̀ Wa

[48] Ṣèrántí (àwọn Ànábì) ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘ àti Thul-Kifl. Ìkọ̀ọ̀kan wọn wà nínú àwọn ẹni rere jùlọ

[49] Èyí ni ìrántí. Àti pé dájúdájú àbọ̀ rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[50] Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére (ni). Wọ́n sì máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn

[51] Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú nínú rẹ̀. Wọn yóò máa bèèrè fún àwọn èso púpọ̀ àti ohun mímu nínú rẹ̀

[52] Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, tí ọjọ́ orí wọn kò jura wọn lọ yó sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn

[53] Èyí ni ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín fún Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́

[54] Dájúdájú èyí ni arísìkí Wa. Kò sì níí tán

[55] Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Àti pé dájúdájú àbọ̀ burúkú ni ti àwọn alágbèéré (sí Allāhu)

[56] Iná Jahanamọ ni wọn yó wọ̀. Ó sì burú ní ibùgbé

[57] Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, kí wọ́n tọ́ ọ wò; omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀

[58] Oríṣiríṣi (ìyà) mìíràn bí irú rẹ̀ (tún wà fún wọn)

[59] Èyí ni ìjọ kan t’ó máa wọ inú Iná pẹ̀lú yín. (Àwọn aṣíwájú nínú Iná sì máa wí pé:) "Kò sí máawolẹ̀-máarọra fún wọn." Dájúdájú wọn yóò wọ inú Iná ni

[60] (Àwọn ọmọlẹ́yìn nínú Iná) máa wí pé: "Rárá, ẹ̀yin náà kò sí máawolẹ̀-máarọra fun yín. Ẹ̀yin l’ẹ pè wá síbi èyí (t’ó bí Iná)." Ó sì burú ní ibùgbé

[61] Wọ́n (tún) wí pé: "Olúwa wa, ẹni tí ó pè wá (síbi ìyà) yìí, ṣe àlékún àdìpèlé ìyà fún un nínú Iná

[62] Wọ́n tún wí pé: "Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wa tí a ò rí àwọn ọkùnrin kan, àwọn tí à ń kà mọ́ àwọn ẹni burúkú

[63] Ṣèbí a fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí àwọn ojú ti fò wọ́n ni (l’a ò fi rí wọn nínú Iná)

[64] Dájúdájú ìyẹn, àríyànjiyàn àwọn èrò inú Iná, òdodo mà ni

[65] Sọ pé: "Èmi ni olùkìlọ̀. Àti pé kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àyàfi Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí

[66] Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì, Alágbára, Aláforíjìn

[67] Sọ pé: "(al-Ƙur’ān) ni ìró ńlá

[68] Ẹ̀yin sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀

[69] Èmi kò sì nímọ̀ nípa àwọn mọlāika tí ó wà ní àyè gíga nígbà tí wọ́n ń ṣàròyé

[70] Kí ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi bí kò ṣe pé èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé

[71] (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: "Dájúdájú Èmi yóò dá abara kan láti inú ẹrùpẹ̀

[72] Nígbà tí Mo bá ṣe é t’ó dọ́gba jálẹ̀ tán, tí Mo sì fẹ́ nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí Mo dá sínú rẹ̀, nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni

[73] Gbogbo àwọn mọlāika pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i

[74] Àyàfi ’Iblīs, tí ó ṣègbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́

[75] (Allāhu) sọ pé: "’Iblīs, kí l’ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí ohun tí Mo fi ọwọ́ Mi méjèèjì dá? Ṣé o ṣègbéraga ni tàbí o wà nínú àwọn ẹni gíga

[76] Ó wí pé: "Èmi lóore jùlọ sí òun; O dá èmi láti ara iná. O sì dá òun láti ara erùpẹ̀ amọ̀

[77] (Allāhu) sọ pé: "Jáde kúrò nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) nítorí pé dájúdájú ìwọ ni ẹni ẹ̀kọ̀

[78] Àti pé dájúdájú ègún Mi yóò wà lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san

[79] (Èṣù) wí pé: "Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí Wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde

[80] (Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn tí wọ́n máa lọ́ lára

[81] títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ

[82] (Èṣù) wí pé: "Mo fi agbára Rẹ búra, dájúdájú èmi yóò kó gbogbo wọn sínú ìṣìnà

[83] àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn ẹni ẹ̀ṣà nínú wọn

[84] (Allāhu) sọ pé: "Òdodo (ni ìbúra Mi), òdodo sì ni Èmi ń sọ, (pé)

[85] dájúdájú Mo máa fi ìwọ àti gbogbo àwọn t’ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn kún inú iná Jahanamọ

[86] Sọ pé: "Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Èmi kò sì sí nínú àwọn onítàn-àròsọ

[87] Kí ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá

[88] Àti pé dájúdájú ẹ máa mọ ìró rẹ̀ (sí òdodo) láìpẹ́

Àwọn Ẹgbẹ́

Surah 39

[1] Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà (ṣẹlẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[2] Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, jọ́sìn fún Allāhu ní olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un

[3] Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́. Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): "A ò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni." Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́

[4] Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ fi ẹnì kan ṣe ọmọ ni, ìbá ṣẹ̀ṣà ohun tí Ó bá fẹ́ (fi ṣọmọ) nínú n̄ǹkan tí Ó dá. Mímọ́ ni fún Un (níbi èyí). Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí

[5] Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ń ti òru bọnú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọnú òru. Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn ń rìn fún gbèdéke àkókò kan. Gbọ́! Òun ni Alágbára, Aláforíjìn

[6] Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Lẹ́yìn náà, Ó dá ìyàwó rẹ̀ láti ara rẹ̀. Ó sì sọ mẹ́jọ kalẹ̀ fun yín nínú ẹran-ọ̀sìn ní takọ-tabo. Ó ń ṣẹ̀dá yín sínú ìyá yín, ẹ̀dá kan lẹ́yìn ẹ̀dá kan nínú àwọn òkùnkùn mẹ́ta. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo

[7] Tí ẹ bá ṣàì moore, dájúdájú Allāhu rọrọ̀ láì sí ẹ̀yin (kò sì ní bùkátà si yín). Kò sì yọ́nú sí àìmoore fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Tí ẹ bá dúpẹ́, Ó máa yọ́nú sí i fun yín. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[8] Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pe Olúwa rẹ̀ ní olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ó máa gbàgbé ohun t’ó ṣe ní àdúà sí (Olúwa rẹ) ṣíwájú. Ó sì máa sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá (ẹlòmíìràn) ní ojú ọ̀nà ẹ̀sìn Rẹ̀ (’Islām). Sọ pé: "Fi àìgbàgbọ́ rẹ jẹ̀gbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn èrò inú Iná

[9] Ǹjẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olùtẹ̀lé ti Allāhu (t’ó jẹ́) olùforíkanlẹ̀ àti olùdìdedúró (lórí ìrun kíkí) ní àwọn àkókò alẹ́, t’ó ń ṣọ́ra fún ọ̀run, t’ó sì ń ní àgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Olúwa rẹ̀ (dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?) Sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n nímọ̀ àti àwọn tí kò nímọ̀ dọ́gba bí? Àwọn onílàákàyè nìkan l’ó ń lo ìrántí

[10] Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Ẹ̀san rere wà fún àwọn t’ó ṣe rere ní ilé ayé yìí. Ilẹ̀ Allāhu sì gbòòrò. Àwọn onísùúrù ni Wọ́n sì máa fún ní ẹ̀san (rere iṣẹ́) wọn láì la ìṣírò lọ

[11] Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu ní ti olùṣe-àfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un

[12] Wọ́n tún pa mí ní àṣẹ pé kí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (nínú) àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi)

[13] Sọ pé: "Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá, tí mo bá fi lè yapa àṣẹ Olúwa mi

[14] Sọ pé: "Allāhu ni èmi yóò máa jọ́sìn fún (mo máa jẹ́) olùṣe-àfọ̀mọ́-ẹ̀sìn mi fún Un

[15] Nítorí náà, kí ẹ jọ́sìn fún ohun tí ẹ bá fẹ́ lẹ́yìn Rẹ̀." Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ará ilé wọn lófò ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́! Ìyẹn, òhun ni òfò pọ́nńbélé

[16] Àwọn àjà Iná máa wà ní òkè wọn. Àwọn àjà yó sì wà ní ìsàlẹ̀ wọn. Ìyẹn ni Allāhu fi ń dẹ́rù ba àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ (báyìí pé:) "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, ẹ bẹ̀rù Mi

[17] Àwọn tí wọ́n yàgò fún àwọn òrìṣà láti jọ́sìn fún un, wọ́n sì ṣẹ́rí padà sí (jíjọ́sìn fún) Allāhu, ìró ìdùnnú ń bẹ fún wọn. Nítorí náà, fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró ìdùnnú

[18] Àwọn t’ó ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé èyí t’ó dára jùlọ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu fi mọ̀nà. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onílàákàyè

[19] Ṣé ẹni tí ọ̀rọ̀ ìyà Iná ti kòlé lórí (nípa àìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣé kò níí wọná ni?) Ṣé ìwọ l’ó máa la ẹni t’ó wà nínú Iná (nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ rẹ̀) ni

[20] Ṣùgbọ́n àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn, tiwọn ni àwọn ilé gíga, tí àwọn ilé gíga tún wà lókè rẹ̀, àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àdéhùn Allāhu ni (èyí). Allāhu kò sì níí yẹ àdéhùn náà

[21] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì mú omi náà bọ́ sínú àwọn òpópónà odò nínú ilẹ̀, lẹ́yìn náà, Ó ń fi mú irúgbìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn jáde, lẹ́yìn náà, (irúgbìn náà) yóò gbẹ, o sì máa rí i ní pípọ́n, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ ọ́ di rírún? Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè

[22] Ǹjẹ́ ẹni tí Allāhu gba ọkàn rẹ̀ láàyè fún ẹ̀sìn ’Islām, tí ó sì wà nínú ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (dà bí aláìgbàgbọ́ bí)? Ègbé ni fún àwọn tí ọkàn wọn le sí ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[23] Allāhu l’Ó sọ ọ̀rọ̀ t’ó dára jùlọ kalẹ̀, (ó jẹ́) Tírà, tí (àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀) jọra wọn ní ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ, tí awọ ara àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn yó sì máa wárìrì nítorí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, awọ ara wọn àti ọkàn wọn yóò máa rọ̀ níbi ìrántí Allāhu. Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sí níí sí afinimọ̀nà kan fún un

[24] Ǹjẹ́ ẹni tí ó máa fojú ara rẹ̀ ko aburú ìyà Iná ní Ọjọ́ Àjíǹde (dà bí ẹni tí ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ́ọ́rọ́wọ́)? Wọn yó sì sọ fún àwọn alábòsí pé: "Ẹ tọ́ ìyà ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò

[25] Àwọn t’ó ṣíwájú wọn pe òdodo nírọ́. Nítorí náà, ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura

[26] Allāhu fún wọn ní àbùkù ìyà tọ́ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀

[27] A sì ti ṣe gbogbo àkàwé fún àwọn ènìyàn nínú al-Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[28] Al-Ƙur’ān ní èdè Lárúbáwá, èyí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò dojú rú (l’A sọ̀kalẹ̀) nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu)

[29] Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀; ẹrúkùnrin kan t’ó wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gá púpọ̀ tí wọ́n ń fà á kiri (kò sì mọ ta ni ó máa dá lóhùn nínú àwọn ọ̀gá rẹ̀) àti (àkàwé) ẹrúkùnrin kan t’ó dá wà gédégbé lábẹ́ ọ̀gákùnrin kan. Ǹjẹ́ àwọn (ẹrú) méjèèjì dọ́gba ní àkàwé bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[30] Dájúdájú ìwọ máa kú. Dájúdájú àwọn náà máa kú

[31] Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bá ara yín ṣe àríyànjiyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín

[32] Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó parọ́ mọ́ Allāhu, t’ó tún pe òdodo nírọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé kì í ṣe Iná ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni

[33] Ẹni tí ó sì mú òdodo wá (ìyẹn, Ànábì Muhammad s.a.w.) àti (àwọn) ẹni t’ó gbà á gbọ́ ní òdodo; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùbẹ̀rù (Allāhu)

[34] Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn ẹni rere

[35] nítorí kí Allāhu lè bá wọn pa aburú tí wọ́n ṣe rẹ́ àti (nítorí) kí Ó lè fi èyí t’ó dára jùlọ sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn

[36] Ṣé Allāhu kò tó fún ẹrúsìn Rẹ̀ ni? Wọ́n sì ń fi àwọn ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́! Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un

[37] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), kò lè sí aṣinilọ́nà fún un. Ṣé Allāhu kọ́ ni Alágbára, Olùgba-ẹ̀san

[38] Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, tí Allāhu bá gbèrò ìnira kan rò mí, ǹjẹ́ wọ́n lè mú ìnira Rẹ̀ kúrò fún mi? Tàbí tí Ó bá gbèrò ìkẹ́ kan sí mi, ǹjẹ́ wọ́n lè dá ìkẹ́ Rẹ̀ dúró bí?" Sọ pé: "Allāhu tó fún mi. Òun sì ni àwọn olùgbáralé ń gbáralé

[39] Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣe tiyín ní àyè yín. Èmi náà ń ṣe tèmi. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ

[40] ẹni tí ìyà tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀ máa dé bá, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí

[41] Dájúdájú Àwa sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo (kí o lè fi ṣe ìrántí) fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn

[42] Allāhu l’Ó ń gba àwọn ẹ̀mí ní àkókò ikú wọn àti (àwọn ẹ̀mí) tí kò kú sójú oorun wọn. Ó ń mú (àwọn ẹ̀mí) tí Ó ti pèbùbù ikú lé lórí mọ́lẹ̀. Ó sì ń fi àwọn yòókù sílẹ̀ títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀

[43] Tàbí wọ́n mú àwọn olùṣìpẹ̀ mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: "(Wọ́n mú wọn ní olùṣìpẹ̀) t’ó sì jẹ́ pé wọn kò ní agbára kan kan, wọn kò sì níí làákàyè

[44] Sọ pé: "Ti Allāhu ni gbogbo ìṣìpẹ̀ pátápátá. TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí

[45] Nígbà tí wọ́n bá dárúkọ Allāhu nìkan ṣoṣo, ọkàn àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ máa sá kúrò (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Nígbà tí wọ́n bá sì dárúkọ àwọn mìíràn (tí wọ́n ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa dunnú

[46] Sọ pé: "Allāhu, Olúpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Ìwọ l’O máa dájọ́ láààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu sí

[47] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú gbogbo n̄ǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ jẹ́ ti àwọn alábòsí àti irú rẹ̀ mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ (tún jẹ́ tiwọn ni), wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn) níbi aburú ìyà ní Ọjọ́ Àjíǹde. (Nígbà yẹn) ohun tí wọn kò lérò máa hàn sí wọn ní ọ̀dọ̀ Allāhu

[48] Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ máa hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà t’ó máa yí wọn po

[49] Nígbà tí ìnira kan ba fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pè Wá. Lẹ́yìn náà, nígbà tí A bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa wí pé: "Wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ ni." Kò sì rí bẹ́ẹ̀, àdánwò ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[50] Àwọn t’ó ṣíwájú wọn kúkú wí (irú) rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀

[51] Aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì bá wọn. Àwọn alábòsí nínú àwọn wọ̀nyí náà, aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ yóò bá wọn. Wọn kò sì níí mórí bọ́

[52] Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo

[53] Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń ṣàforíjìn gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[54] Ẹ ṣẹ́rí padà (ní ti ìronúpìwàdà) sí ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Un ṣíwájú kí ìyà náà t’ó wá ba yín. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́

[55] Kí ẹ sì tẹ̀lé ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín ní òjijì, nígbà tí ẹ̀yin kò níí fura

[56] Nítorí kí ẹ̀mí kan má baà wí pé: "Mo ká àbámọ̀ lórí bí mo ṣe jáfara lórí àìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu. Àti pé èmi wà nínú àwọn t’ó ń fi (ọ̀rọ̀ Rẹ̀) ṣe yẹ̀yẹ́

[57] Tàbí kí ó má baà wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fi ọ̀nà mọ̀ mí ni, dájúdájú èmi ìbá wà nínú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[58] Tàbí nígbà tí ó bá rí Iná kí ó má baà wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé ìpadàsáyé wà fún mi ni, èmi ìbá sì wà nínú àwọn olùṣe-rere

[59] Rárá o! Àwọn āyah Mi kúkú ti dé bá ọ. O pè é nírọ́. O tún ṣègbéraga. O sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́

[60] Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí àwọn t’ó parọ́ mọ́ Allāhu tí ojú wọn máa dúdú. Ṣé inú iná Jahnamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn onígbèéraga ni

[61] Allāhu yóò gba àwọn t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) là sínú ilé ìgbàlà wọn (ìyẹn, Ọgbà Ìdẹ̀ra). Aburú kò níí fọwọ́ bà wọ́n. Wọn kò sì níí banújẹ́

[62] Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan

[63] TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ àpótí-ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò

[64] Sọ pé: "Ṣé n̄ǹkan mìíràn yàtọ̀ sí Allāhu l’ẹ̀ ń pa mí lásẹ pé kí n̄g máa jọ́sìn fún, ẹ̀yin aláìmọ̀kan

[65] Dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ (pé) "Dájúdájú tí o bá ṣẹbọ, iṣẹ́ rẹ máa bàjẹ́. Dájúdájú o sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò

[66] Rárá (má ṣẹbọ). Allāhu nìkan ni kí o jọ́sìn fún. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un)

[67] Wọn kò bu iyì fún Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bu iyì fún Un. Gbogbo ilẹ̀ pátápátá sì ni (Allāhu) máa fọwọ́ ara Rẹ̀ gbámú ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ká sánmọ̀ kóróbójó. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[68] Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún ikú. Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ sì máa kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn

[69] Àti pé ilẹ̀ náà yóò máa tàn yànrànyànràn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá lélẹ̀. Wọ́n sì máa mú àwọn Ànábì àti àwọn ẹlẹ́rìí wá. A ó sì ṣèdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú òdodo. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[70] Àti pé Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[71] Wọn yó sì da àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lọ sínú iná Jahnamọ níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjíṣẹ́ kan kò wá ba yín láti ààrin ara yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Olúwa yín fun yín, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ ìpàdé ọjọ́ yín òní yìí fun yín?" Wọ́n wí pé: "Rárá (wọ́n wá bá wa)." Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìyà kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ni

[72] A óò sọ pé: "Ẹ wọ ẹnu ọ̀nà iná Jahnamọ. Olùṣegbére (ni yín) nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn olùṣègbéraga sì burú

[73] Àti pé A óò kó àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn lọ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: "Kí àlàáfíà máa ba yín. Ẹ̀yin ṣe iṣẹ́ t’ó dára. Nítorí náà, ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, (kí ẹ di) olùṣegbére (nínú rẹ̀)

[74] Wọ́n á sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún wa. Ó tún jogún ilẹ̀ náà fún wa, tí à ń gbé níbikíbi tí a bá fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra." Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere mà sì dára

[75] O máa sì rí àwọn Mọlāika tí wọ́n ń rọkiriká ní ẹ̀gbẹ́ Ìtẹ́-ọlá. Wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin àwọn ẹ̀dá. Wọ́n sì máa sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

Olùdáríjì

Surah 40

[1] Hā mīm

[2] Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Onímọ̀

[3] Aláforíjìn-ẹ̀ṣẹ̀, Olùgba-ìronúpìwàdà, Ẹni líle níbi ìyà, Ọlọ́rẹ, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni àbọ̀ ẹ̀dá

[4] Kò sí ẹni tí ó máa ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu àfi àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn nínú ìlú kó ẹ̀tàn bá ọ

[5] Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)

[6] Àti pé báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe kò lórí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Dájúdájú àwọn ni èrò inú Iná

[7] Àwọn t’ó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n gba Allāhu gbọ́. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): "Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm

[8] Olúwa wa, fi wọ́n sínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí Ó ṣe ní àdéhùn fún àwọn àti ẹni t’ó ṣe iṣẹ́ rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn aya wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[9] Ṣọ́ wọn nínú àwọn aburú. Ẹnikẹ́ni tí O bá ṣọ́ níbi àwọn aburú (ìyà) ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú O ti kẹ́ ẹ. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá

[10] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): " Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́

[11] Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Nítorí náà, a sì jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí

[12] (Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi

[13] Òun ni Ẹni t’Ó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àfi ẹni t’ó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà)

[14] Nítorí náà, ẹ pe Allāhu ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀

[15] (Allāhu) Ẹni t’Ó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí (al-Ƙur’ān) ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà

[16] Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): "Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní? Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni

[17] Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́

[18] Àti pé ṣèkìlọ̀ ọjọ́ tí ó súnmọ́ fún wọn. Nígbà tí àwọn ọkàn bá ga dé gògòńgò, tí ó máa kún fún ìbànújẹ́, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ àti olùṣìpẹ̀ kan tí wọ́n máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí (ọ̀rọ̀) àwọn alábòsí

[19] (Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́

[20] Àti pé Allāhu l’Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran

[21] Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu

[22] Ìyẹn nítorí pé àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ẹni líle níbi ìyà

[23] Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí t’ó yanjú rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́

[24] sí Fir‘aon, Hāmọ̄n àti Ƙọ̄rūn. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: "Òpìdán, òpùrọ́ ni (Ànábì Mūsā)

[25] Nígbà tí ó mú òdodo náà dé ọ̀dọ̀ wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Ẹ pa àwọn ọmọkùnrin àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin wọn sílẹ̀." Ète àwọn aláìgbàgbọ́ kò sí nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò

[26] Fir‘aon wí pé: "Ẹ fi mí sílẹ̀ kí n̄g pa Mūsā, kí ó sì pe Olúwa rẹ̀ (wò bóyá Ó máa gbà á sílẹ̀). Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé ó máa yí ẹ̀sìn yín padà tàbí pé ó máa ṣàfi hàn ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀

[27] (Ànábì) Mūsā sọ pé: "Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò gba Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́ gbọ́

[28] Ọkùnrin onígbàgbọ́ òdodo kan t’ó ń fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ pamọ́ nínú àwọn ènìyàn Fir‘aon sọ pé: "Ṣé ẹ máa pa ọkùnrin kan nítorí pé ó ń sọ pé, ‘Allāhu ni Olúwa mi.’ Ó sì kúkú ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Tí ó bá jẹ́ òpùrọ́, (ìyà) irọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ olódodo, apá kan èyí tí ó ṣe ní ìlérí fun yín yó sì kò le yín lórí. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́

[29] Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ̀yin l’ẹ ni ìjọba lónìí, ẹ̀yin sì ni alásẹ lórí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ta ni ó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìyà Allāhu bá dé bá wa?" Fir‘aon wí pé: "Èmi kò fi n̄ǹkan kan hàn yín bí kò ṣe ohun tí mo rí (nínú òye mi). Èmi kò sì tọ yín sí ọ̀nà kan bí kò ṣe ojú ọ̀nà ìmọ̀nà

[30] Ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú irú ọjọ́ (ẹ̀san ìyà t’ó ṣẹlẹ̀ sí) àwọn ọmọ-ogun oníjọ ni èmi ń páyà lórí yín

[31] Irú ìṣe (ìparun t’ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn) ènìyàn Nūh, ‘Ād, Thamūd àti àwọn t’ó tẹ̀lé wọn. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí sí àwọn ẹrúsìn náà

[32] Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi ń páyà Ọjọ́ ìpè fun yín

[33] Ọjọ́ tí ẹ máa pẹ̀yìndà láti sá lọ; kò sì níí sí aláàbò kan fun yín lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un

[34] Àti pé dájúdájú (Ànábì) Yūsuf ti tọ̀ yín wá ṣíwájú pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ t’ó yanjú, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yé wà nínú iyèméjì nípa ohun tí ó mú wá ba yín títí di ìgbà tí ó fi kú, tí ẹ fi wí pé: "Allāhu kò níí gbé Òjíṣẹ́ kan dìde mọ́ lẹ́yìn rẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, oníyèméjì nù

[35] Àwọn t’ó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìsí ẹ̀rí kan tí ó dé bá wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni ní ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní ọ̀dọ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo gbogbo ọkàn onígbèéraga, ajẹninípá.”

[36] Fir‘aon wí pé: "Hāmọ̄n, mọ ilé gíga fíofío kan fún mi nítorí kí èmi lè dé àwọn ojú ọ̀nà náà

[37] Àwọn ojú ọ̀nà (inú) sánmọ̀ ni, nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā nítorí pé dájúdájú èmi ń rò ó sí òpùrọ́." Báyẹn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú (ọwọ́) Fir‘aon ní ọ̀ṣọ́ fún un. Wọ́n sì ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Ète Fir‘aon kò sì wà nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò

[38] Ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé mi, mo máa júwe yín sí ojú ọ̀nà ìmọ̀nà

[39] Ẹ̀yin ènìyàn mi, ìṣẹ̀mí ilé ayé yìí jẹ́ ìgbádùn lásán. Dájúdájú ọ̀run sì ni ilé gbére

[40] Ẹni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè àrísìkí fún wọn nínú rẹ̀ láì la ìṣírò lọ

[41] Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ló mú yín tí mò ń pè yín síbi ìgbàlà, tí ẹ̀yin sì ń pè mí síbi Iná

[42] Ẹ̀ ń pè mí pé kí n̄g ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí n̄g sì sọ n̄ǹkan tí èmi kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Un. Èmi sì ń pè yín sí ọ̀dọ̀ Alágbára, Aláforíjìn

[43] Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè mí sí, kò ní ẹ̀tọ́ sí ìpè kan ní ayé àti ní ọ̀run. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni àbọ̀ wa. Dájúdájú àwọn olùtayọ-ẹnu-àlà, àwọn ni èrò inú Iná

[44] Nítorí náà, ẹ máa rántí ohun tí mò ń sọ fun yín. Mo sì ń fi ọ̀rọ̀ mi tì sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn

[45] Allāhu sì ṣọ́ ọ níbi àwọn aburú tí wọ́n dète rẹ̀. Ìyà burúkú sì yí àwọn ènìyàn Fir‘aon po

[46] Iná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): "Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná t’ó le jùlọ

[47] (Rántí) nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn ṣe àríyànjiyàn nínú Iná. Àwọn ọ̀lẹ yóò wí fún àwọn tí wọ́n ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé ìpín kan kúrò fún wa nínú ìyà Iná?”

[48] Àwọn t’ó ṣègbéraga wí pé: "Dájúdájú gbogbo wa l’a wà nínú rẹ̀.” Dájúdájú Allāhu kúkú ti dájọ́ láààrin àwọn ẹrú náà

[49] Àwọn t’ó wà nínú Iná tún wí fún àwọn ẹ̀ṣọ́-Iná pé: "Ẹ bá wa pe Olúwa yín, kí Ó ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wa fún ọjọ́ kan

[50] Wọ́n yóò sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjísẹ́ yín kì í mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín bí?" Wọ́n wí pé: “Rárá, (wọ́n ń mú un wá).” Wọ́n sọ pé: “Ẹ ṣàdúà wò.” Àdúà àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà. ọ̀nà wo ni àwọn aláìgbàgbọ́ ń gbà rí oore láyé? Kò sí oore ayé kan tí ó lè tẹ aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ bí kò ṣe ìpín rẹ̀ nínú kádàrá. Àmọ́ ní ti onígbàgbọ́ òdodo oore inú kádàrá àti oore àdúà l’ó wà fún un níwọ̀n ìgbà tí àdúà rẹ̀ bá ti bá sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) mu

[51] Dájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde)

[52] Ní ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn

[53] Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní ìmọ̀nà. A sì jogún Tírà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl

[54] (Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè

[55] Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù. àwọn tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú sílẹ̀ wọ̀nyí àwọn ni olórí àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah. Wọ́n sì ti pa àwọn mùsùlùmí kan nípakúpa ṣíwájú kí ọwọ́ tó tẹ àwọn náà lójú ogun Badr. Àmọ́ ohun tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rò t’ó fi tú wọn sílẹ̀ ni pé ‘Ó gba ìyàwó lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀ ó sì fi ṣaya!’. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé a ò gbọ́dọ̀ fojú bín-íntín wo èyíkéyìí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ kún fún títọrọ àforíjìn ni lọ́dọ̀ Allāhu Aláforíjìn. Kò sí ohun t’ó dára tó rírí àforíjìn gbà lọ́dọ̀ Allāhu lórí gbogbo àṣìṣe wa ṣíwájú ọjọ́ ikú wa

[56] Dájúdájú àwọn t’ó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran

[57] Dájúdájú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tóbi ju ìṣẹ̀dá àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀

[58] Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere àti oníṣẹ́-aburú (kò dọ́gba). Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí

[59] Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́

[60] Olúwa yín sọ pé: "Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ

[61] Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fun yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un)

[62] Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo

[63] Báyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn t’ó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn)

[64] Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ibùgbé. Ó mọ sánmọ̀ (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[65] Òun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un. Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[66] Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[67] Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè

[68] Òun ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀

[69] Ṣé o ò rí àwọn tí ń ṣàríyànjiyàn nípa àwọn āyah Allāhu bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo

[70] Àwọn t’ó pe Tírà náà àti ohun tí A fi rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa nírọ́, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀

[71] Nígbà tí àwọn sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n bá wà ní ọrùn wọn, tí wọn yóò fi máa wọ́ wọn

[72] sínú omi gbígbóná. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi wọ́n ko Iná

[73] Lẹ́yìn náà, Wọ́n máa sọ fún wọn pé: "Ibo ni ohun tí ẹ sọ di òrìṣà wà

[74] (Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?" Wọ́n á wí pé: "Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà

[75] Ìyẹn nítorí pé ẹ̀ ń yọ lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣe fáàrí (lórí àìgbàgbọ́)

[76] Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀na iná Jahanamọ; olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó sì burú ní ibùgbé fún àwọn onígbèéraga

[77] Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí

[78] Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A ò sì sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn

[79] Allāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fun yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn

[80] Àwọn àǹfààní (mìíràn) wà fun yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn t’ó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ ó sì máa fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù

[81] (Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l’ẹ máa takò

[82] Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà)

[83] Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun t’ó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po

[84] Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: "A gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un

[85] Ìgbàgbọ́ wọn kò ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn

Tí a ṣàlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́

Surah 41

[1] Hā mīm

[2] Ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí kan (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[3] (Èyí ni) Tírà kan tí Wọ́n ṣàlàyé àwọn āyah inú rẹ̀; al-Ƙur’ān ní èdè Lárúbáwá ni fún ìjọ t’ó nímọ̀

[4] (Ó jẹ́) ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gbúnrí kúrò níbẹ̀. Wọn kò sì tẹ́tí sí i

[5] Wọ́n sì wí pé: "Ọkàn wa wà ní títì pa sí ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí. Èdídí sì wà nínú etí wa. Àti pé gàgá wà láààrin àwa àti ìwọ. Nítorí náà, máa ṣe tìrẹ. Dájúdájú àwa náà ń ṣe tiwa

[6] Sọ pé: "Abara bí irú yín kúkú ni èmi náà. Wọ́n ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi ni, pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin tì Í, kí ẹ sì tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ègbé sì ni fún àwọn ọ̀ṣẹbọ

[7] àwọn tí kò yọ Zakāh. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn

[8] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pẹ̀dín ń bẹ fún wọn

[9] Sọ pé: "Ṣé dájúdájú ẹ̀yin máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ fún ọjọ́ méjì, ẹ sì ń sọ (ẹ̀dá Rẹ̀) di akẹgbẹ́ fún Un?" Ìyẹn sì ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[10] Ó sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin. (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀). ó jẹyọ nínú wọn pé “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:54 n̄ǹkan náà kò níí dòhun àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”. Àwọn ẹ̀dá tí kò bá sì jẹmọ́ èròjà ìṣẹ̀dá tàbí àwọn ẹ̀dá tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sọ nípa èròjà ìṣẹ̀dá wọn fún wa Allāhu l’Ó kúkú nímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ àwọn ẹ̀dá kan di ẹ̀dá pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn” nìkan. Àwọn ẹ̀dá kan sì di ẹ̀dá nípasẹ̀ èròjà ìṣẹ̀dá àti gbólóhùn “kunfayakūn”. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀nà tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà gbólóhùn “kunfayakūn” t’ó jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoṣo kò lè sọ Allāhu di olùkánjú. Ìkánjú kì í ṣe ìròyìn rere fún Allāhu. Bí Allāhu ṣe gbàròyìn pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”

[11] Lẹ́yìn náà, Allāhu wà ní òkè sánmọ̀, nígbà tí sánmọ̀ wà ní èéfín. Ó sì sọ fún òhun àti ilẹ̀ pé: "Ẹ wá bí ẹ fẹ́ tàbí ẹ kọ̀." Àwọn méjèèjì sọ pé: "A wá pẹ̀lú ìfínnú-fíndọ̀

[12] Ó sì parí (ìṣẹ̀dá) rẹ̀ sí sánmọ̀ méje fún ọjọ́ méjì. Ó sì fi iṣẹ́ sánmọ̀ kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sínú rẹ̀. A sì fi àwọn àtùpà (ìràwọ̀) ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ àti ààbò (fún un). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀

[13] Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ pé: "Èmi ń ṣèkìlọ̀ ìparun irú ìparun ìjọ ‘Ād àti Thamūd fun yín ni

[14] Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn níwájú wọn àti lẹ́yìn wọn, (wọ́n sọ) pé: "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu." Wọ́n wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa wa bá fẹ́ ni, ìbá sọ mọlāika kalẹ̀ (fún ìpèpè yìí). Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́

[15] Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì wí pé: "Ta ni ó lágbára jù wá lọ ná?" Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu tí Ó ṣẹ̀dá wọn, Ó ní agbára jù wọ́n lọ ni. Wọ́n sì ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Wa

[16] Nítorí náà, A rán atẹ́gùn líle sí wọn ní àwọn ọjọ́ burúkú kan nítorí kí Á lè jẹ́ kí wọ́n tọ́ ìyà yẹpẹrẹ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì máa yẹpẹrẹ wọn jùlọ; Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́. “ọjọ́ kan” di “àwọn ọjọ́ kan” nínú āyah ti sūrah Fussilat. Àmọ́ àpapọ̀ òǹkà ọjọ́ ìparun wọn l’ó jẹyọ nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh. Ṣé ẹ ti rí i báyìí pé àìnímọ̀ nípa èto láààrin àwọn āyah lè ṣokùnfà ìtakora āyah lójú aláìmọ̀kan

[17] Ní ti ìjọ Thamūd, A ṣàlàyé ìmọ̀nà fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àìríran dípò ìmọ̀nà. Nítorí náà, igbe ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá gbá wọn mú nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[18] A sì gba àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu) là

[19] Ní ọjọ́ tí wọ́n máa kó àwọn ọ̀tá Allāhu jọ síbi Iná, wọn yó sì kó àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn papọ̀ mọ́ àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn

[20] títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀ tán, ìgbọ́rọ̀ wọn, ìríran wọn àti awọ ara wọn yó sì máa jẹ́rìí lé wọn lórí nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[21] Wọn yóò wí fún awọ ara wọn pé: "Nítorí kí ni ẹ ṣe jẹ́rìí lé wa lórí ná?" Wọ́n yóò sọ pé: "Allāhu, Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ọ̀rọ̀ sọ, Òun l’Ó fún wa ní ọ̀rọ̀ sọ. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí

[22] Ẹ̀yin kò lè para yín mọ́ (kúrò níbi ẹ̀ṣẹ̀, nítorí) kí ìgbọ́rọ̀ yín, ìríran yín àti awọ ara yín má fi lè jẹ́rìí le yín lórí. Ṣùgbọ́n ẹ lérò pé dájúdájú Allāhu kò mọ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[23] Ìyẹn, èrò yín tí ẹ lérò sí Olúwa yín ló kó ìparun ba yín. Ẹ sì di ẹni òfò

[24] Tí wọ́n bá ṣe sùúrù (fún ìyà), Iná kúkú ni ibùgbé fún wọn. Tí wọ́n bá sì fẹ́ ṣẹ́rí padà sí ṣíṣe ohun tí Allāhu yọ́nú sí (ní àsìkò yìí), A ò níí gbà wọ́n láyè láti ṣẹ́rí padà

[25] Àwa ti yan àwọn alábàárìn kan fún wọn, tí wọ́n ṣe ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí (bí ó ṣe ṣẹlẹ̀) sí àwọn ìjọ t’ó ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànǹú àti ènìyàn pé dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò

[26] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Ẹ má ṣe tẹ́tí sí al-Ƙur’ān yìí. Kí ẹ sì sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀ kí ẹ lè borí

[27] Nítorí náà, dájúdájú A óò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ níyà líle tọ́ wò. Àti pé dájúdájú A óò fi èyí t’ó burú ju èyí tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san

[28] Iná, ìyẹn ni ẹ̀san àwọn ọ̀tá Allāhu. Ilé gbére wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ó jẹ́ ẹ̀san nítorí pé wọ́n ń tako àwọn āyah Wa

[29] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Olúwa wa, fi àwọn méjèèjì tí wọ́n ṣì wá lọ́nà nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn hàn wá nítorí kí á lè fi àwọn méjèèjì sí abẹ́ gìgísẹ̀ wa, nítorí kí wọ́n lè wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá

[30] Dájúdájú àwọn t’ó sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa." lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin, àwọn mọlāika yóò máa sọ̀kalẹ̀ wá bá wọn (ní ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì máa sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà, ẹ má ṣe banújẹ́. Kí ẹ sì dunnú sí Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín)

[31] Àwa ni ọ̀rẹ́ yín nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní ọ̀run. Ohun tí ẹ̀mí yín ń fẹ́ ti wà fun yín nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún sì ti wà nínú rẹ̀

[32] N̄ǹkan ìgbàlejò ni láti ọ̀dọ̀ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

[33] Ta ni ó dára jùlọ ní ọ̀rọ̀ sísọ t’ó tayọ ẹni tí ó pèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ṣe iṣẹ́ rere, tí ó sì sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn mùsùlùmí

[34] Rere àti aburú kò dọ́gba. Fi èyí tí ó dára jùlọ dènà (aburú). Nígbà náà ni ẹni tí ọ̀tá wà láààrin ìwọ àti òun máa dà bí ọ̀rẹ́ alásùn-únmọ́ pẹ́kípẹ́kí

[35] A ò níí fún ẹnì kan ní (ìwà rere yìí) àfi àwọn t’ó ṣe sùúrù. A ò níí fún ẹnì kan sẹ́ àfi olórí-ire ńlá

[36] Àti pé tí èròkérò kan láti ọ̀dọ̀ Èṣù bá fẹ́ ṣẹ́ ọ lórí (kúrò níbi ìwà rere yìí), sá di Allāhu. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[37] Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni òru, ọ̀sán, òòrùn àti òṣùpá. Ẹ ò gbọdọ̀ forí kanlẹ̀ fún òòrùn àti òṣùpá. Ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tí Ó dá wọn, tí ẹ̀yin bá jẹ́ ẹni t’ó ń jọ́sìn fún Òun nìkan ṣoṣo

[38] Tí wọ́n bá sì ṣègbéraga, àwọn t’ó wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní alẹ́ àti ní ọ̀sán; wọn kò sì kágara

[39] Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó jí i, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[40] Dájúdájú àwọn t’ó ń yẹ àwọn āyah Wa (síbi òmíràn), wọn kò pamọ́ fún Wa. Ṣé ẹni tí wọ́n máa jù sínú Iná l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó máa wá ní olùfàyàbalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde? Ẹ máa ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[41] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Tírà Ìrántí náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) nígbà tí ó dé bá wọn (ẹni ìparun ni wọ́n.) Dájúdájú òhun mà ni Tírà t’ó lágbára

[42] Ìbàjẹ́ kò níí kàn án láti iwájú rẹ̀ àti láti ẹ̀yìn rẹ̀. Ìmísí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Ẹlẹ́yìn

[43] Wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan sí ọ bí kò ṣe ohun tí wọ́n ti sọ sí àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ. Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Ó sì ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro (lọ́dọ̀)

[44] Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe al-Ƙur’ān ní n̄ǹkan kíké ní èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá ni, wọn ìbá wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n ṣe àlàyé àwọn āyah rẹ̀?" Báwo ni al-Ƙur’ān ṣe lè jẹ́ èdè mìíràn (yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá), nígbà tí Ànábì (Muhammad s.a.w.) jẹ́ Lárúbáwá? Sọ pé: "Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìwòsàn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Àwọn tí kò sì gbàgbọ́, èdídí wà nínú etí wọn. Fọ́júǹfọ́jú sì wà nínú ojú wọn sí (òdodo al-Ƙur’ān). Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n sì ń pè (síbi òdodo al-Ƙur’ān) láti àyè t’ó jìnnà

[45] A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa ẹnu sí i. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ́ kan tí ó ti ṣíwájú ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, A ìbá ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n tún wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa al-Ƙur’ān

[46] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn

[47] Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò máa dá ìmọ̀ Àkókò náà padà sí. Kò sí èso kan tí ó máa jáde nínú apó rẹ̀, obìnrin kan kò sì níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Ó sì máa pè wọ́n pé: "Ibo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi (tí ẹ jọ́sìn fún) wà?" Wọ́n á wí pé: "Àwa ń jẹ́ kí O mọ̀ pé kò sí olùjẹ́rìí kan nínú wa (tí ó máa jẹ́rìí pé O ní akẹgbẹ́)

[48] Ohun tí wọ́n ń pè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sì dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́. Wọ́n sì mọ̀ ní àmọ̀dájú pé kò sí ibùsásí kan fún àwọn

[49] Ènìyàn kò kó ṣúṣú níbi àdúà (láti tọrọ) oore. Tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù, olùjákànmùná

[50] Dájúdájú tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Wa lẹ́yìn aburú tí ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: "Èyí ni tèmi. Èmi kò sì ní àmọ̀dájú pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé dájúdájú tí Wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú rere tún wà fún mi ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀." Dájúdájú Àwa yóò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú A sì máa fún wọn ní ìyà t’ó nípọn tọ́ wò

[51] Àti pé nígbà tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò ní ọ̀dọ̀ Wa). Ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, nígbà náà l’ó máa di aládùáà rẹgẹdẹ

[52] Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, lẹ́yìn náà tí ẹ ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ (ṣé ẹ̀yin kò ti wà nínú ìyapa bí?)" Ta l’ó ṣìnà ju ẹni tí ó wà nínú ìyapa t’ó jìnnà (sí òdodo)

[53] A óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan

[54] Gbọ́, dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìpàdé Olúwa wọn. Gbọ́, dájúdájú Allāhu yí gbogbo n̄ǹkan ká

Ìmọ̀ràn

Surah 42

[1] Hā mīm

[2] ‘Aēn sīn ƙọ̄f

[3] Báyẹn ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n ṣe ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ

[4] TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ó ga, Ó tóbi

[5] Sánmọ̀ fẹ́ẹ̀ fàya láti òkè wọn (nípa títóbi Allāhu). Àwọn mọlāika sì ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn t’ó wà lórí ilẹ̀. Gbọ́ Mi, dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[6] Àwọn t’ó mú àwọn alátìlẹ́yìn kan lẹ́yìn Rẹ̀, Allāhu sì ni Aláàbò lórí wọn. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn

[7] Báyẹn ni A ṣe fi al-Ƙur’ān ránṣẹ́ sí ọ ní èdè Lárúbáwá nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù), àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ nípa Ọjọ́ Àkójọ, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìjọ kan yóò wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ìjọ kan yó sì wà nínú Iná t’ó ń jò

[8] Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe wọ́n ní ìjọ ẹlẹ́sìn ẹyọ kan. Ṣùgbọ́n Ó ń fi ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Àwọn alábòsí, kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn

[9] Ṣé wọ́n mú àwọn aláàbò kan lẹ́yìn Rẹ̀ ni? Allāhu, Òun sì ni Aláàbò. Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[10] Ohunkóhun tí ẹ bá yapa ẹnu nípa rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa mi. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí padà sí (ní ti ìronúpìwàdà). ọ̀rọ̀ Allāhu àti ìdájọ́ Rẹ̀. Pẹ̀lú àgbọ́yé yìí āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah t’ó ń pa wá láṣẹ láti fi al-Ƙur’an àti sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) yanjú àwọn ọ̀rọ̀ ìyapa-ẹnu

[11] (Òun ni) Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ṣẹ̀dá àwọn obìnrin fun yín láti ara yín. Ó tún ṣẹ̀dá àwọn abo ẹran-ọ̀sìn láti ara àwọn akọ ẹran-ọ̀sìn. Ó ń mu yín pọ̀ sí i (nípa ìṣẹ̀dá yín ní akọ-abo). Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran

[12] TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ àpótí-ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[13] (Allāhu) ṣe ní òfin fun yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà)

[14] (Àwọn ọ̀ṣẹbọ) kò sì pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tí ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (pé Òun yóò lọ́ wọn lára) títí di gbèdéke àkókò kan ni, Wọn ìbá ti dájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú àwọn tí A jogún Tírà fún lẹ́yìn wọn sì tún wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa ’Islām

[15] Nítorí ìyẹn, pèpè (sínú ’Islām), kí o sì dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí Wọ́n ṣe pa ọ́ lásẹ. Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Kí o sì sọ pé: "Mo gbàgbọ́ nínú èyíkéyìí Tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Wọ́n sì pa mí láṣẹ pé kí n̄g ṣe déédé láààrin yín. Allāhu ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kò sí ìjà láààrin àwa àti ẹ̀yin. Allāhu l’Ó sì máa kó wa jọ papọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ní àbọ̀ ẹ̀dá.”

[16] Àwọn t’ó ń bá (Ànábì s.a.w.) jà nípa (ẹ̀sìn) Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ènìyàn ti gbà fún un, ẹ̀rí wọn máa wó lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Ìbínú ń bẹ lórí wọn. Ìyà líle sì wà fún wọn

[17] Allāhu ni Ẹni tí Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) àti (òfin) òṣùwọ̀n (déédé) kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Àti pé kí l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí Àkókò náà ti súnmọ́

[18] Àwọn tí kò gbà á gbọ́ ń wá a pẹ̀lú ìkánjú. Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ ní òdodo ń páyà rẹ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni. Kíyè sí i, dájúdájú àwọn t’ó ń jiyàn nípa Àkókò náà ti wà nínú ìṣìnà t’ó jìnnà

[19] Allāhu ni Aláàánú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Abiyì

[20] Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ọ̀run, A máa ṣe àlékún sí èso rẹ̀ fún un. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ayé, A máa fún un nínú rẹ̀. Kò sì níí sí ìpín kan kan fún un mọ́ ní ọ̀run

[21] Tàbí wọ́n ní àwọn òrìṣà kan t’ó ṣòfin (ìbọ̀rìṣà) fún wọn nínú ẹ̀sìn, èyí tí Allāhu kò yọ̀ǹda rẹ̀? Tí kò bá jẹ́ ti ọ̀rọ̀ àsọyán (pé A ò níí kánjú jẹ wọ́n níyà), Àwa ìbá ti mú ìdájọ́ wá láààrin wọn. Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[22] O máa rí àwọn alábòsí tí wọn yóò máa páyà nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, tí ó sì máa kò lé wọn lórí. Àwọn t’ó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere máa wà ní àwọn àyè t’ó rẹwà jùlọ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn, òhun ni oore àjùlọ t’ó tóbi

[23] Ìyẹn ni èyí tí Allāhu fi ń ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Sọ pé: "Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ bí kò ṣe ìfẹ́ ẹbí.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe rere kan, A máa ṣe àlékún rere fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́

[24] Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni?" Nítorí náà, tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa fi èdídí dí ọkàn rẹ pa. Àti pé Allāhu yóò pa irọ́ rẹ́. Ó sì máa fi òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[25] Òun ni Ẹni t’Ó ń gba ìronúpìwàdà àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe àmójúkúrò níbi àwọn àṣìṣe. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[26] Ó ń gba àdúà àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Ó sì ń ṣe àlékún fún wọn nínú ọlá Rẹ̀. Àwọn aláìgbàgbọ́, ìyà líle sì wà fún wọn

[27] Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni, wọn ìbá tayọ ẹnu-àlà lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń sọ (arísìkí) tí Ó bá fẹ́ kalẹ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀

[28] Òun sì ni Ẹni t’Ó ń sọ omi òjò kalẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti sọ̀rètí nù. Ó sì ń fọ́n ìkẹ́ Rẹ̀ ká. Òun sì ni Aláàbò, Ẹlẹ́yìn

[29] Àti pé nínú àmì Rẹ̀ ni ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tí Ó fọ́nká sáààrin méjèèjì nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí. Òun sì ni Alágbára lórí ìkójọ wọn nígbà tí Ó bá fẹ́

[30] Ohunkóhun tí ó bá kàn yín nínú àdánwò, ohun tí ẹ fi ọwọ́ ara yín fà ni. Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀

[31] Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́ (mọ́ Allāhu lọ́wọ́) lórí ilẹ̀. Kò sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu

[32] Ó tún wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn lójú omi (t’ó dà) bí àwọn òkè àpáta gíga

[33] Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa mú atẹ́gùn náà dúró, (àwọn ọkọ̀ ojú-omi náà) sì máa di ohun tí kò níí lọ mọ́ lórí omi. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́

[34] Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa mú atẹ́gùn náà dúró, (àwọn ọkọ̀ ojú-omi náà) sì máa di ohun tí kò níí lọ mọ́ lórí omi. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́

[35] Àwọn t’ó ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Wa sì máa mọ̀ pé kò sí ibùsásí kan fún wọn

[36] Nítorí náà, ohunkóhun tí A bá fun yín, ìgbádùn ayé nìkan ni. Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa ṣẹ́kù títí láéláé fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn

[37] (Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn t’ó ń jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá àti àwọn ìwà ìbàjẹ́, àti (àwọn t’ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá bínú, wọ́n yóò ṣàforíjìn

[38] (Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn t’ó jẹ́pè ti Olúwa wọn, tí wọ́n ń kírun, ọ̀rọ̀ ara wọn sì jẹ́ ìjíròrò láààrin ara wọn, wọ́n tún ń ná nínú arísìkí tí A pèsè fún wọn

[39] (Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí wọn, wọn yóò gbẹ̀san wọn padà

[40] Ẹ̀san aburú sì ni aburú bí irú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàmójúkúrò, tí ó tún ṣàtúnṣe, ẹ̀san rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí

[41] Dájúdájú ẹni tí ó bá sì gbẹ̀san lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àbòsí sí i, àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ṣàbòsí sí), kò sí ìbáwí kan kan fún wọn

[42] Àwọn tí ìbáwí wà fún ni àwọn t’ó ń ṣàbòsí sí àwọn ènìyàn, tí wọ́n tún ń tayọ ẹnu-àlà lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún

[43] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe sùúrù, tí ó tún ṣàforíjìn, dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ t’ó pọn dandan

[44] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò tún sí aláàbò kan fún un mọ́ lẹ́yìn Rẹ̀. O sì máa rí àwọn alábòsí nígbà tí wọ́n bá rí Iná, wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ ọ̀nà kan kan wà tí a lè fi padà sí ilé ayé

[45] O sì máa rí wọn tí A máa kó wọn lọ sínú Iná; wọn yóò palọ́lọ́ láti ara ìyẹpẹrẹ, wọn yó si máa wò fín-ín-fín. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ara ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde." Kíyè sí i, dájúdájú àwọn alábòsí yóò wà nínú ìyà gbére

[46] Kò sì níí sí aláàbò kan fún wọn tí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Àti pé ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí ọ̀nà kan kan fún un

[47] Ẹ jẹ́pè Olúwa yín ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó de, tí kò sí ìdápadà kan fún un ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Kò sí ibùsásí kan fun yín ní ọjọ́ yẹn. Kò sì níí sí olùkọ̀yà kan fun yín

[48] Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, A ò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ fún wọn. Kò sí kiní kan t’ó di dandan fún ọ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́. Àti pé dájúdájú nígbà tí A bá fún ènìyàn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn án nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọn tì ṣíwájú (ní iṣẹ́ aburú), dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore

[49] Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó ń ta ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́rẹ ọmọbìnrin. Ó sì ń ta ẹni tí Ó bá fẹ́ ní lọ́rẹ ọmọkùnrin

[50] Tàbí kí Ó ṣe wọ́n ní oríṣi méjì; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ó sì ń ṣe ẹni tí Ó bá fẹ́ ní àgàn. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀, Alágbára

[51] Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan pé kí Allāhu bá a sọ̀rọ̀ àfi kí (ọ̀rọ̀ náà) jẹ́ ìmísí (ìṣípayá mímọ́), tàbí kí ó jẹ́ lẹ́yìn gàgá, tàbí kí Ó rán Òjíṣẹ́ kan (tí)

[52] Báyẹn sì ni A ṣe fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ nínú àṣẹ Wa. Ìwọ kò mọ kí ni Tírà àti ìgbàgbọ́ òdodo tẹ́lẹ̀ (ṣíwájú ìmísí náà),1 ṣùgbọ́n A ṣe ìmísí náà ní ìmọ́lẹ̀ kan tí À ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí A bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Dájúdájú ìwọ ń pèpè sí ọ̀nà tààrà (’Islām). 2 iṣẹ́ wiridi ni Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) máa ń ṣe nínú ọ̀gbun Hirā ṣíwájú kí ó tó di Ànábì Ọlọ́hun irọ́ l’ó fi pa. Ìdí ni pé

[53] Ọ̀nà Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Gbọ́! Ọ̀dọ̀ Allāhu ni àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá yóò padà sí

Ọ̀ṣọ́ wúrà

Surah 43

[1] Hā mīm

[2] (Allāhu) fi Tírà t’ó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra

[3] Dájúdájú Àwa sọ ọ́ ní al-Ƙur’ān. (A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní) èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè

[4] Àti pé dájúdájú nínú Tírà Ìpìlẹ̀ t’ó wà lọ́dọ̀ Wa, al-Ƙur’ān ga, ó kún fún ọgbọ́n

[5] Ṣé kí Á ká Tírà Ìrántí (al-Ƙur’ān) kúrò nílẹ̀ fun yín, kí Á máa wò yín níran nítorí pé ẹ jẹ́ ìjọ alákọyọ

[6] Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí A ti rán sí àwọn ẹni àkọ́kọ́

[7] Kò sí Ànábì kan tí ó wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́

[8] Nítorí náà, A ti pa àwọn t’ó ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) rẹ́. Àpèjúwe (ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì ti ṣíwájú

[9] Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Ẹni t’ó dá wọn ni Alágbára, Onímọ̀

[10] Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ fun yín. Ó sì fi àwọn ojú ọ̀nà sínú rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà

[11] Ẹni tí Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Ó sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀. Báyẹn náà ni wọn yóò ṣe mu yín jáde

[12] Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi. Ó sì ṣe n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gùn fun yín láti ara àwọn ọkọ̀ ojú-omi àti àwọn ẹran-ọ̀sìn

[13] Nítorí kí ẹ lè jókòó dáadáa sẹ́yìn rẹ̀, lẹ́yìn náà kí ẹ lè ṣe ìrántí ìdẹ̀ra Olúwa yín nígbà tí ẹ bá jókòó dáadáa tán sórí rẹ̀, kí ẹ sì sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó rọ èyí fún wa, kì í ṣe pé a jẹ́ alágbára lórí rẹ̀

[14] Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa yóò padà sí

[15] Wọ́n fi ìpín kan nínú àwọn ẹrúsìn (Allāhu) tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (ní ti ọmọ bíbí). Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore pọ́nńbélé

[16] Tàbí (ẹ̀yin ń wí pé): "Ó mú nínú n̄ǹkan tí Ó dá ní ọmọbìnrin (fúnra Rẹ̀). Ó sì fi àwọn ọmọkùnrin ṣa ẹ̀yin lẹ́ṣà

[17] Nígbà tí wọ́n bá fún ẹnì kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú ohun tí ó fi ṣe àpẹẹrẹ fún Àjọkẹ́-ayé (pé onítọ̀ún bí ọmọbìnrin), ojú rẹ̀ máa ṣókùnkùn wá. Ó sì máa kún fún ìbànújẹ́

[18] Ṣé ẹni tí wọ́n ń tọ́ nínú ọ̀ṣọ́ (tí ó ń to ọ̀ṣọ́ mọ́ra), tí kò sì lè bọ́ sí gban̄gba níbi ìjà (ni ẹ̀ ń pè ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé)

[19] Àwọn mọlāika, àwọn t’ó jẹ́ ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé, wọ́n tún sọ wọ́n di ọmọbìnrin! Ṣé wọ́n fojú rí ìṣẹ̀dá wọn ni? Wọ́n máa ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n fojú rí. Wọ́n sì máa bi wọ́n léèrè (nípa rẹ̀)

[20] Wọ́n tún wí pé: "Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́, àwa ìbá tí jọ́sìn fún wọn." Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa ìyẹn. Wọn kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́

[21] Tàbí A ti fún wọn ní Tírà kan ṣíwájú al-Ƙur’ān, tí wọ́n ń lò ní ẹ̀rí

[22] Rárá. Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùmọ̀nà lórí orípa wọn

[23] Bákan náà, Àwa kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan ṣíwájú rẹ, àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùtẹ̀lé wọn lórí orípa wọn

[24] (Olùkìlọ̀) sì sọ pé: "Ǹjẹ́ èmi kò ti mú wá fun yín ohun tí ó jẹ́ ìmọ̀nà jùlọ sí ohun tí ẹ bá àwọn bàbá yín lórí rẹ̀?" Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́

[25] Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn. Wo bí ìkángun àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ ti rí

[26] (Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún

[27] Àfi Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Dájúdájú Òun l’Ó máa fi ọ̀nà tààrà mọ̀ mí

[28] Allāhu sì ṣe é ní ọ̀rọ̀ kan t’ó máa wà títí láéláé láààrin àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo)

[29] Ṣùgbọ́n Mo fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn ayé títí òdodo àti Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé fi dé bá wọn

[30] Nígbà tí òdodo dé bá wọn, wọ́n wí pé: "Idán ni èyí; dájúdájú àwa kò sì níí gbà á gbọ́

[31] Wọ́n tún wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin pàtàkì kan nínú àwọn ìlú méjèèjì

[32] Ṣé àwọn ni wọn máa pín ìkẹ́ Olúwa rẹ ni? Àwa l’A pín n̄ǹkan ìṣẹ̀mí wọn fún wọn nínú ìgbésí ayé. A sì fi àwọn ipò gíga gbé apá kan wọn ga ju apá kan lọ nítorí kí apá kan wọn lè máa ṣiṣẹ́ fún apá kan. Ìkẹ́ Olúwa rẹ sì lóore jùlọ sí ohun tí wọ́n ń kó jọ

[33] Àti pé tí kì í bá ṣe pé àwọn ènìyàn máa jẹ́ ìjọ kan ṣoṣo (lórí àìgbàgbọ́ ni), A ìbá ṣe àwọn òrùlé àti àwọn àkàbà tí wọn yóò fi máa gùnkè nínú ilé ní fàdákà fún ẹni t’ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé

[34] (A ìbá tún ṣe) àwọn ẹnu ọ̀nà ilé wọn àti àwọn ibùsùn tí wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú lé lórí (ní fàdákà)

[35] àti góòlù. Gbogbo n̄ǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé lásán. (Ọgbà Ìdẹ̀ra) Ọ̀run sì wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[36] Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọké-ayé, A máa yan èṣù kan fún un. Òun sì ni alábàárìn rẹ̀

[37] Dájúdájú àwọn èṣù náà yóò máa ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Wọn yó sì máa lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà

[38] Títí di ìgbà tí ó fi máa wá bá Wa, ó sì máa wí pé: "Háà! Kí ó sì jẹ́ pé (ìtakété bí) ìtakété ibùyọ-òòrùn àti ibùwọ̀ rẹ̀ sì wà láààrin èmi àti ìwọ (èṣù alábàárìn yìí, ìbá dára); alábàárìn burúkú sì ni

[39] (Àbámọ̀ yín) kò níí ṣe yín ní àǹfààní ní Òní nígbà tí ẹ ti ṣàbòsí. (Àti pé) dájúdájú ẹ̀yin (àti òrìṣà yín) ni akẹ́gbẹ́ nínú ìyà

[40] Ṣé ìwọ l’o máa fún àwọn adití ní ọ̀rọ̀ gbọ́ tàbí o máa fún àwọn afọ́jú ní ìmọ̀nà àti ẹni tí ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[41] Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Á ti mú ọ kúrò (lórí ilẹ̀ ayé ṣíwájú àsìkò ìyà wọn), dájúdájú Àwa yóò gbẹ̀san (ìyà) lára wọn

[42] Tàbí kí Á fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́, dájúdájú Àwa jẹ́ Alágbára lórí wọn

[43] Nítorí náà, di ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ mú ṣinṣin. Dájúdájú ìwọ wà lójú ọ̀nà tààrà (’Islām)

[44] Dájúdájú al-Ƙur’ān ni tírà ìrántí fún ìwọ àti ìjọ rẹ. Láìpẹ́ Wọ́n máa bi yín léèrè (nípa rẹ̀)

[45] Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa (pé): "Ǹjẹ́ A sọ àwọn kan di ọlọ́hun tí wọn yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé bí

[46] A kúkú fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ó sì sọ pé: "Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[47] Ṣùgbọ́n nígbà tí ó mú àwọn àmì Wa wá bá wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àmì náà rẹ́rìn-ín nígbà náà

[48] A ò sì níí fi àmì kan hàn wọ́n àyàfi kí ó tóbi ju irú rẹ̀ (t’ó ṣíwájú). A sì fi ìyà jẹ wọ́n nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo)

[49] Wọ́n sì wí pé: "Ìwọ òpìdán, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe pẹ̀lú rẹ. Dájúdájú àwa máa tẹ̀lé ìmọ̀nà Rẹ̀

[50] Ṣùgbọ́n nígbà tí A mú ìyà kúrò fún wọn, nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn

[51] Fir‘aon sì pèpè láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀, ó wí pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ṣé tèmi kọ́ ni ìjọba Misrọ àti àwọn odò wọ̀nyí t’ó ń ṣàn nísàlẹ̀ (ọ̀dọ̀) mi? Ṣé ẹ ò ríran ni

[52] Tàbí ṣé èmi kò lóore jùlọ sí èyí tí ó jẹ́ ọ̀lẹ yẹpẹrẹ, tí ó fẹ́ẹ̀ má lè dá ọ̀rọ̀ sọ yanjú

[53] Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní àwọn ẹ̀gbà-ọwọ́ góòlù tàbí (kí ni kò jẹ́ kí) àwọn mọlāika wá pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n jẹ́ alábàárìn (tí wọn yóò máa jẹ́rìí rẹ̀)

[54] Nítorí náà, ó sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ dòpè. Wọ́n sì tẹ̀lé e. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[55] Nígbà tí wọ́n wá ìbínú Wa, A gba ẹ̀san (ìyà) lára wọn. Nítorí náà, A tẹ gbogbo wọn rì (sínú agbami odò)

[56] A sì ṣe wọ́n ní ìjọ aṣíwájú (nínú ìparun) àti àpẹẹrẹ (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn

[57] Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ọmọ Mọryam ṣe àpẹẹrẹ (fún òrìṣà wọn), nígbà náà ni àwọn ènìyàn rẹ bá ń fi (àpẹẹrẹ náà) rẹ́rìn-ín

[58] Wọ́n sì wí pé: "Ṣé àwọn òrìṣà wa l’ó lóore jùlọ ni tàbí òun? Wọn kò wulẹ̀ fi ṣàpẹẹrẹ fún ọ bí kò ṣe (fún) àtakò. Àní sẹ́, ìjọ oníyànjíjà ni wọ́n

[59] Kí ni òun bí kò ṣe ẹrúsìn kan tí A ṣe ìdẹ̀ra fún. A sì ṣe é ní àpẹẹrẹ rere fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl

[60] Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, A ìbá máa fi àwọn mọlāika rọ́pò yín lórí ilẹ̀

[61] Dájúdájú òun ni ìmọ̀ (tàbí àmì fún ìsúnmọ́) Àkókò náà. Nítorí náà, ẹ ò gbọdọ̀ ṣeyèméjì nípa rẹ̀. Kí ẹ sì tẹ̀lé mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà

[62] Ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù ṣẹ yín lórí; dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín

[63] Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā dé pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ó sọ pé: "Dájúdájú mo dé wá ba yín pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n. (Mo sì dé) nítorí kí n̄g lè ṣe àlàyé apá kan èyí tí ẹ̀ ń yapa ẹnu nípa rẹ̀ fun yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[64] Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà

[65] Àwọn ìjọ (rẹ̀) sì yapa (ẹ̀sìn ’Islām) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàbòsí ní ọjọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[66] Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà; tí ó máa dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura

[67] Àwọn ọ̀rẹ́ àyò ní ọjọ́ yẹn, apá kan wọn yóò jẹ́ ọ̀tá fún apá kan àyàfi àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[68] Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, kò sí ìbẹ̀rù fun yín ní òní. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́

[69] (Àwọn ni) àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì jẹ́ mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu)

[70] Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ẹ̀yin àti àwọn ìyàwó yín; kí ẹ máa dunnú

[71] Wọn yóò máa gbé àwọn àwo góòlù àti àwọn ife ìmumi káà kiri ọ̀dọ̀ wọn. Ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́ àti (ohun tí) ojú yóò máa dúnnú sí wà nínú rẹ̀. Olùṣegbére sì ni yín nínú rẹ̀

[72] Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fun yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[73] Èso púpọ̀ wà fun yín nínú rẹ̀. Ẹ̀yin yó sì máa jẹ nínú rẹ̀

[74] Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni olùṣegbére nínú ìyà iná Jahanamọ

[75] A ò níí gbé e fúyẹ́ fún wọn. Wọn yó sì sọ̀rètí nù nínú Iná

[76] A ò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n jẹ́ alábòsí

[77] Wọn yóò pe (mọlāika kan) pé: "Mọ̄lik (ẹ̀ṣọ́ Iná), jẹ́ kí Olúwa rẹ pa wá ráúráú." (Mọ̄lik) yóò sọ pé: "Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbé inú rẹ̀ ni

[78] Dájúdájú A ti mú òdodo wá ba yín, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yin kórira òdodo

[79] Tàbí àwọn (aláìgbàgbọ́) ti pinnu ọ̀rọ̀ kan ni? Dájúdájú Àwa náà ń pinnu ọ̀rọ̀

[80] Tàbí wọ́n ń lérò pé Àwa kò gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn? Rárá (À ń gbọ́); àwọn Òjíṣẹ́ Wa wà ní ọ̀dọ̀ wọn, tí wọ́n ń ṣe àkọsílẹ̀ (ọ̀rọ̀ wọn)

[81] Sọ pé: "Kò sí ọmọ kan fún Àjọké ayé. Nítorí náà, èmi ni ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu ní àsìkò tèmi)

[82] Mímọ́ ni fún Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Olúwa Ìtẹ́-ọlá tayọ irọ́ tí wọ́n ń pa (mọ́ Ọn)

[83] Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré wọn lọ títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn, tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

[84] (Allāhu) Òun ni Ọlọ́hun Ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí nínú sánmọ̀. Òun náà sì ni Ọlọ́hun Ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí lórí ilẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

[85] Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa da yín padà sí

[86] Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò kápá ìṣìpẹ̀ àyàfi ẹni tí ó bá jẹ́rìí sí òdodo (kalmọtuṣ-ṣahaadah), tí wọ́n sì nímọ̀ (rẹ̀)

[87] Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá wọn?", dájúdájú wọn á wí pé: "Allāhu ni." Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo

[88] Ọ̀rọ̀ (tí Ànábì ń sọ fún Allāhu ni pé): "Olúwa Mi, dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ tí kò gbàgbọ́.”

[89] Nítorí náà, ṣàmójú kúrò fún wọn, kí ó sì sọ pé: "Àlàáfíà!" Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀

Èéfín

Surah 44

[1] Hā mīm

[2] (Allāhu) búra pẹ̀lú Tírà t’ó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá

[3] Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú òru ìbùkún. Dájúdájú Àwa ń jẹ́ Olùkìlọ̀

[4] Nínú òru náà ni wọ́n ti máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò níí tàsé (lórí ẹ̀dá)

[5] Àṣẹ kan ni láti ọ̀dọ̀ Wa. Dájúdájú Àwa l’À ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́

[6] Ìkẹ́ kan ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[7] Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú

[8] Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́

[9] Síbẹ̀, wọ́n sì wà nínú iyèméjì, tí wọ́n ń ṣeré

[10] Nítorí náà, máa retí ọjọ́ tí sánmọ̀ yóò mú èéfín pọ́nńbélé wá

[11] Ó máa bo àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀. Èyí ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[12] (Àwọn ènìyàn yóò wí pé): Olúwa wa, gbé ìyà náà kúrò fún wa, dájúdájú àwa yóò gbàgbọ́ ní òdodo

[13] Báwo ni ìrántí ṣe lè wúlò fún wọn (lásìkò ìyà)? Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé kúkú ti dé bá wọn

[14] Lẹ́yìn náà, wọ́n gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì wí pé: "Wèrè tí ènìyàn kan ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ni

[15] Dájúdájú Àwa máa gbé ìyà náà kúrò fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹ̀yin yóò tún padà (sínú àìgbàgbọ́)

[16] Ọjọ́ tí A óò gbá (wọn mú) ní ìgbámú t’ó tóbi jùlọ; dájúdájú Àwa yóò gba ẹ̀san ìyà (lára wọn)

[17] Dájúdájú A dán àwọn ènìyàn Fir‘aon wò ṣíwájú wọn. Òjíṣẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé sì dé wá bá wọn

[18] (Ó sọ pé): “Ẹ kó àwọn ẹrúsìn Allāhu lé mi lọ́wọ́. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín

[19] Ẹ má ṣe ṣègbéraga sí Allāhu. Dájúdájú èmi ti mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá ba yín

[20] Dájúdájú Èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín pé kí ẹ má ṣe sọ mí lókò pa

[21] Tí ẹ kò bá sì gbà mí gbọ́, ẹ fi mí sílẹ̀ jẹ́

[22] Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ ẹlẹ́sẹ̀

[23] (Allāhu sọ pé): "Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní alẹ́ (nítorí pé) wọn yóò tọ̀ yín lẹ́yìn

[24] Kí o sì fi agbami odò sílẹ̀ ní yíyanu sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Dájúdájú àwọn ni ọmọ ogun tí A máa tẹ̀rì sínú agbami

[25] Mélòó mélòó nínú àwọn ọgbà oko àti odò ìṣẹ́lẹ̀rú tí wọ́n fi sílẹ̀ (lẹ́yìn ìparun wọn)

[26] Àti àwọn irúgbìn pẹ̀lú àyè àpọ́nlé (tí wọ́n fi sílẹ̀)

[27] Àti ìdẹ̀ra tí wọ́n ń gbádùn nínú rẹ̀ (ṣíwájú ìparun wọn)

[28] Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe rí). A sì jogún (ìlú) wọ́n fún ìjọ ènìyàn mìíràn

[29] Nígbà náà, sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sunkún wọn. Wọn kò sì fi ìyà wọn falẹ̀

[30] Dájúdájú A gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là nínú ìyà yẹpẹrẹ

[31] (A là wọ́n) lọ́wọ́ Fir‘aon. Dájúdájú ó jẹ́ onígbèéraga. Ó sì wà nínú àwọn alákọyọ

[32] A kúkú ṣà wọ́n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn) pẹ̀lú ìmọ̀

[33] A sì fún wọn ní àwọn àmì tí àdánwò pọ́nńbélé wà nínú rẹ̀

[34] Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ń wí pé

[35] Kò sí ikú kan àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí ó pa wá nílé ayé). Wọn kò sì níí gbé wa dìde

[36] (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́), ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[37] Ṣé àwọn ni wọ́n lóore jùlọ ni tàbí àwọn ènìyàn Tubba‘u àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn? A pa wọ́n rẹ́; dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀

[38] A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe

[39] A kò dá àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[40] Dájúdájú ọjọ́ òpínyà (ìyẹn, ọjọ́ àjíǹde) ni àkókò àdéhùn fún gbogbo wọn pátápátá

[41] Ní ọjọ́ tí ọ̀rẹ́ kan kò níí fi kiní kan rọ ọ̀rẹ́ kan lọ́rọ̀. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́

[42] Àyàfi ẹni tí Allāhu bá kẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[43] Dájúdájú igi zaƙūm

[44] ni oúnjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀

[45] Ó dà bí epo gbígbá tí ń hó nínú ikùn

[46] (t’ó) dà bí híhó omi gbígbóná

[47] Ẹ mú un. Kí ẹ wọ́ ọ sáàrin gbùngbùn inú iná Jẹhīm

[48] Lẹ́yìn náà, ẹ rọ́ ìyà olómi gbígbóná lé e lórí

[49] Tọ́ ọ wò (ṣebí) dájúdájú ìwọ ni alágbára, alápọ̀n-ọ́nlé (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pe ara rẹ)

[50] Dájúdájú (ìyà) èyí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀

[51] Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà ní àyè ìfàyàbalẹ̀

[52] (Wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀)

[53] Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àti àrán t’ó nípọn; wọn yó sì máà kọjú síra wọn

[54] Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn yó ṣe rí). A sì máa fi àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ ṣe ìyàwó fún wọn

[55] Wọn yóò máa bèèrè fún gbogbo n̄ǹkan eléso nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀

[56] Wọn kò níí tọ́ ikú wò níbẹ̀ àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí wọ́n ti kú nílé ayé). (Allāhu) sì máa ṣọ́ wọn níbi ìyà iná Jẹhīm

[57] Ó jẹ́ oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá

[58] Nítorí náà, A ṣe (al-Ƙur’ān) ní ìrọ̀rùn lórí ahọ́n rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí

[59] Nítorí náà, máa retí . Dájúdájú àwọn náà ń retí

Títẹríba

Surah 45

[1] Hā mīm

[2] Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[3] Dájúdájú nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àwọn àmì wà (nínú wọn) fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[4] Àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá yín àti ohun tí Allāhu ń fọ́nká (sórí ilẹ̀) nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ t’ó ní àmọ̀dájú

[5] (Nínú) ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní arísìkí, tí Ó ń fi sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn t’ó ti kú àti ìyípadà atẹ́gùn, àwọn àmì tún wà (nínú wọn) fún ìjọ t’ó ní làákàyè

[6] Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu tí À ń ké (ní kéú) fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ wo lẹ́yìn (ọ̀rọ̀) Allāhu àti àwọn àmì Rẹ̀ ni wọn yóò tún gbàgbọ́

[7] Ègbé ni fún aládàápaarọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀

[8] t’ó ń gbọ́ àwọn āyah Allāhu, tí wọ́n ń ké e fún un, lẹ́yìn náà, tí ó (tún) takú ní ti ìgbéraga bí ẹni pé kò gbọ́ ọ. Fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[9] Nígbà tí ó bá nímọ̀ nípa kiní kan nínú àwọn āyah Wa, ó máa mú un ní n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá ń bẹ fún

[10] Iná Jahanamọ wà níwájú wọn. Ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n mú ní aláàbò lẹ́yìn Allāhu kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan níbi ìyà. Ìyà ńlá sì wà fún wọn

[11] Èyí ni ìmọ̀nà. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn, ìyà ẹlẹ́gbin ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn

[12] Allāhu ni Ẹni tí Ó rọ agbami odò fun yín nítorí kí àwọn ọkọ̀ ojú-omi lè rìn nínú rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ tún lè wá nínú oore Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)

[13] Ó tún rọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ pátápátá fun yín láti ọ̀dọ̀ ara Rẹ̀. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní àròjinlẹ̀

[14] Sọ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé kí wọ́n ṣàmójú kúrò fún àwọn tí kò retí àwọn ọjọ́ (tí) Allāhu (yóò ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo) nítorí kí Ó lè san ẹ̀san fún ìjọ kan nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[15] Ẹníkẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn yóò da yín padà sí

[16] Dájúdájú A fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní Tírà àti ìdájọ́ ṣíṣe pẹ̀lú ipò Ànábì. A sì ṣe arísìkí fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. A sì ṣoore àjùlọ fún wọn lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò wọn)

[17] A tún fún wọn ní àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú nípa ọ̀rọ̀ náà. Nítorí náà, wọn kò pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń yapa ẹnu sí

[18] Lẹ́yìn náà, A fi ọ́ sí ojú ọ̀nà kan nínú ọ̀rọ̀ (ẹ̀sìn ’Islām). Nítorí náà, tẹ̀lé e. Kí o sì má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn tí kò nímọ̀

[19] Dájúdájú wọn kò lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kiní kan níbi ìyà ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú àwọn alábòsí, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan. Allāhu sì ni Ọ̀rẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)

[20] Èyí ni ìtọ́sọ́nà fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún ìjọ t’ó ní àmọ̀dájú

[21] Tàbí àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé A máa ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí (A ti ṣe) àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kí ìṣẹ́mí ayé wọn àti ikú wọn rí bákan náà? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú

[22] Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo àti nítorí kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn

[23] Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀, tí Allāhu sì ṣì í lọ́nà pẹ̀lú ìmọ̀ , tí Ó sì fi èdídí dí ìgbọ́rọ̀ rẹ̀ àti ọkàn rẹ̀, tí Ó tún fi èbìbò bo ojú rẹ̀! Ta ni ó máa fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n lẹ́yìn Allāhu? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni

[24] Wọ́n wí pé: "Kò sí ìṣẹ̀mí kan mọ́ bí kò ṣe ìṣẹ̀mí ayé wa yìí; à ń kú, a sì ń ṣẹ̀mí. Àti pé kò sí n̄ǹkan t’ó ń pa wá bí kò ṣe ìgbà." Wọn kò sì ní ìmọ̀ kan nípa ìyẹn; wọn kò ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń ro èròkérò

[25] Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwíjàre wọn kò jẹ́ kiní kan tayọ kí wọ́n wí pé: "Ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[26] Sọ pé: "Allāhu l’Ó ń sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀

[27] Àti pé ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀; ọjọ́ yẹn ni àwọn t’ó ń tẹ̀lé irọ́ yóò ṣòfò

[28] O sì máa rí gbogbo ìjọ lórí ìkúnlẹ̀. Wọn yó sì máa pe ìjọ kọ̀ọ̀kan síbi ìwé iṣẹ́ wọn. Ní òní ni A óò san yín ní ẹ̀san ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[29] Èyí ni ìwé àkọ́sílẹ̀ Wa, tí ó ń sọ òdodo nípa yín. Dájúdájú Àwa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[30] Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ pọ́nńbélé

[31] Ní ti àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, (A óò bi wọ́n léèrè pé:) "Ǹjẹ́ wọn kì í ké àwọn āyah Mi fun yín bí?" Ṣùgbọ́n ẹ ṣègbéraga. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀

[32] Nígbà tí wọ́n bá sọ pé: "Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé Àkókò náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀." Ẹ̀yin ń wí pé: "Àwa kò mọ ohun tí Àkókò náà jẹ́. Àwa kò sì rò ó sí kiní kan bí kò ṣe èròkérò; àwa kò sì ní àmọ̀dájú (nípa rẹ̀)

[33] Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po

[34] Wọ́n sì máa sọ pé: "Ní òní, Àwa yóò gbàgbé yín (sínú Iná) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Iná sì ni ibùgbé yín. Àti pé kò níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fun yín

[35] Báyẹn ni nítorí pé, ẹ sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àti pé ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Nítorí náà, ní òní wọn kò níí mú wọn jáde kúrò nínú Iná. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu

[36] Nítorí náà, gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[37] TiRẹ̀ ni títóbi nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

Àwọn Ìyàngbẹ Ilẹ̀

Surah 46

[1] Hā mīm

[2] Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[3] A ò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa gbúnrí kúrò níbi ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn

[4] Sọ pé: "Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun t’ó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi t’ó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[5] Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tí ó ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹni tí kò lè jẹ́ ìpè rẹ̀ títí di Ọjọ́ Àjíǹde! Àti pé wọn kò ní òye sí pípè tí wọ́n ń pè wọ́n

[6] Nígbà tí A bá sì kó àwọn ènìyàn jọ (fún Àjíǹde), àwọn òrìṣà yóò di ọ̀tá fún àwọn abọ̀rìṣà. Wọ́n sì máa tako ìjọ́sìn tí wọ́n ṣe fún wọn

[7] Nígbà tí wọ́n bá ń ké áwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa sọ ìsọkúsọ sí òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: "Èyí ni idán pọ́nńbélé

[8] Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni." Sọ pé: "Tí mo bá hun ún fúnra mi, ẹ ò ní ìkápá kiní kan fún mi ní ọ̀dọ̀ Allāhu (níbi ìyà Rẹ̀). Òun ni Onímọ̀-jùlọ nípa ìsọkúsọ tí ẹ̀ ń sọ nípa rẹ̀. Ó (sì) tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[9] Sọ pé: "Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé." wọ́n wà lábẹ́ ìjọba àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí níí yọwọ́ kọ́wọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Lásìkò náà ipò ọ̀lẹ ni àwọn mùsùlùmí wà nínú ìlú náà. Kò sí ohun t’ó wá lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ sínú ’Islām tayọ kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ìjìyà àti pípa han àwọn mùsùlùmí ni èèmọ̀ ìfojú-egbò-rìn. Mọ̀ dájú pé kò sí Ànábì kan nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun (ahm.s.w.) tí kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé ìtúmọ̀ tí àwọn kristiẹni fún āyah náà l’ó bá jẹ́ òdodo “èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí Allāhu máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” ni ìbá jẹ́ àgbékalẹ̀ rẹ̀. Bákan náà iṣẹ́ tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ fáyé kò yàtọ̀ sí ti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (ahm.s.w). Bákan náà āyah náà ń pè wá síbi ìdúró ṣinṣin àti àtẹ̀mọra lásìkò ìnira àwọn aláìgbàgbọ́

[10] Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni (al-Ƙur’ān) ti wá, tí ẹ sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ẹlẹ́rìí kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì jẹ́rìí lórí irú rẹ̀, tí ó sì gbà á gbọ́, (àmọ́) tí ẹ̀yin ṣègbéraga sí i, (ṣé ẹ ò ti ṣàbòsí báyẹn bí?). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[11] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān jẹ́ oore ni, wọn kò níí ṣíwájú wa débẹ̀." Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kò ti tẹ̀lé ìmọ̀nà rẹ̀, ni wọ́n ń wí pé: "Irọ́ ijọ́un ni èyí

[12] Tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn. Al-Ƙur’ān) yìí tún ni Tírà kan t’ó ń jẹ́rìí sí òdodo ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn t’ó ṣàbòsí, (ó sì jẹ́) ìró ìdùnnú fún àwọn olùṣe-rere

[13] Dájúdájú àwọn t’ó sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa", lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin, kò níí sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́

[14] Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[15] A pa á ní àsẹ fún ènìyàn pé kí ó máa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Ìyá rẹ̀ ní oyún rẹ̀ pẹ̀lú wàhálà. Ó sì bí i pẹ̀lú wàhálà. Oyún rẹ̀ àti gbígba ọmú lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n oṣù. (Ó sì ń tọ́ ọ) títí ó fi dàgbà, tí ó fi di ọmọ ogójì ọdún, ó sì sọ pé: "Olúwa mi, fi mọ̀ mí kí n̄g máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí Ó fi ṣe ìdẹ̀ra fún mi àti fún àwọn òbí mi méjèèjì, kí n̄g sì máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Kí O sì ṣe rere fún mi lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi. Dájúdájú èmi ti ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú èmi sì wà nínú àwọn mùsùlùmí

[16] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A máa gba iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa ṣe àmójúkúrò níbi àwọn aburú iṣẹ́ wọn; wọ́n máa wà nínú àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

[17] Ẹni tí ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì pé: "Ṣíọ̀ ẹ̀yin méjèèjì! Ṣé ẹ̀yin yóò máa ṣèlérí fún mi pé Wọn yóò mú mi jáde (láàyè láti inú sàréè), ṣebí àwọn ìran kan ti ré kọjá lọ ṣíwájú mi (tí Wọn kò tí ì mú wọn jáde láti inú sàréè wọn)." Àwọn (òbí rẹ̀) méjèèjì sì ń tọrọ ìgbàlà ní ọ̀dọ̀ Allāhu (fún ọmọ yìí. Wọ́n sì sọ pé): "Ègbé ni fún ọ! (O jẹ́) gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo." (Ọ̀mọ̀ náà sì) wí pé: "Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́

[18] Àwọn (aláìgbàgbọ́) wọ̀nyẹn ni àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí nínú àwọn ìjọ kan tí ó ti ré kọjá ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò

[19] Àwọn ipò yóò wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Àti pé (èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Àwa kò sì níí ṣàbòsí sí wọn

[20] Ní ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kọ Iná, (wọ́n máa sọ fún wọn pé:) "Ẹ ti lo ìgbádùn yín tán nínú ìṣẹ̀mí ayé? Ẹ sì ti jẹ ìgbádùn ayé? Nítorí náà, ní òní, wọ́n máa san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí pé ẹ̀ ń ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣèbàjẹ́

[21] Ṣèrántí arákùnrin (ìjọ) ‘Ād. Nígbà tí ó ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ t’ó ń gbé nínú yanrìn tí atẹ́gùn kójọ bí òkè. Àwọn olùkìlọ̀ sì ti ré kọjá ṣíwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀. (Ó sì sọ pé:) "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá kan fun yín

[22] Wọ́n wí pé: "Ṣé ìwọ wá bá wa láti ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi àwọn òrìṣà wa ni? Mú ohun tí ò ń ṣe ìlérí rẹ̀ fún wa wá tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo

[23] Ó sọ pé: "Ìmọ̀ (nípa rẹ̀) wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo. Èmi yó sì jẹ́ iṣẹ́ tí Wọ́n fi rán mi dé òpin fun yín, ṣùgbọ́n èmi ń ri ẹ̀yin ní ìjọ aláìmọ̀kan

[24] Nígbà tí wọ́n rí ìyà náà ní ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, t’ó ń wọ́ bọ̀ wá sínú àwọn kòtò ìlú wọn, wọ́n wí pé: "Èyí ni ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, tí ó máa rọ̀jò fún wa." Kò sì rí bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ni. Atẹ́gùn tí ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà nínú rẹ̀ ni

[25] Ó ń pa gbogbo n̄ǹkan rẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n di ẹni tí wọn kò rí mọ́ àfi àwọn ibùgbé wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san

[26] A kúkú fún wọn ní ipò tí A ò fún ẹ̀yin. A sì fún wọn ní ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn. Àmọ́ ìgbọ́rọ̀ wọn àti àwọn ìríran wọn pẹ̀lú àwọn ọkàn wọn kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan níbi ìyà nítorí pé wọ́n ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po

[27] Àwa kúkú ti pa rẹ́ nínú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká yín. Àwa sì ti ṣàlàyé àwọn āyah náà ní oríṣiríṣi ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo)

[28] Àwọn ọlọ́hun tí wọ́n sọ di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ (ìgbàlà) lẹ́yìn Allāhu kò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́? Rárá (kò lè sí àrànṣe fún wọn)! Wọ́n ti dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìyẹn sì ni (ọlọ́hun) irọ́ wọn àti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́

[29] (Rántí) nígbà tí A darí ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú sí ọ, tí wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ al-Ƙur’ān. Nígbà tí wọ́n dé síbẹ̀, wọ́n sọ pé: "Ẹ dákẹ́ (fún al-Ƙur’ān)." Nígbà tí wọ́n sì parí (kíké rẹ̀ tán), wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ wọn, tí wọ́n ń ṣèkìlọ̀ (fún wọn)

[30] Wọ́n sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ wa, dájúdájú àwa gbọ́ (nípa) Tírà kan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn (Ànábì) Mūsā, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀, tí ó sì ń tọ́ni sí ọ̀nà òdodo àti ọ̀nà tààrà

[31] Ẹ̀yin ìjọ wa, ẹ jẹ́ ìpè olùpèpè Allāhu. Kí ẹ sì gbà á gbọ́ ní òdodo. (Allāhu) yó sì forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa yọ yín kúrò nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[32] Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì jẹ́pè olùpèpè Allāhu, kò lè mórí bọ́ mọ́ (Allāhu) lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Kò sì sí aláàbò kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[33] Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí kò sì káàárẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá wọn, (ṣé kò) ní agbára láti sọ àwọn òkú di alààyè ni? Rárá, (Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[34] (Rántí) ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lọ sórí Iná, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé:) "Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?" Wọn yóò wí pé: "Rárá, (òdodo ni) Olúwa wa." (Allāhu máa) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́

[35] Nítorí náà, ṣe sùúrù gẹ́gẹ́ bí àwọn onípinnu ọkàn nínú àwọn Òjíṣẹ́ ti ṣe sùúrù. Má ṣe bá wọn wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú. Ní ọjọ́ tí wọ́n bá rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, wọn yóò dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé (yìí) tayọ àkókò kan nínú ọ̀sán. Al-Ƙur’ān yìí sì ni ìjíṣẹ́ dópin. Ta ni ó sì máa parun bí kò ṣe ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

Muhammad

Surah 47

[1] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, (Allāhu) máa sọ iṣẹ́ wọn dòfò

[2] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n tún gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) Muhammad, òhun sì ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (Allāhu) máa pa àwọn (iṣẹ́) aburú wọn rẹ́, Ó sì máa ṣe àtúnṣe ọ̀rọ̀ wọn sí dáadáa

[3] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ tẹ̀lé irọ́. Àti pé dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ tẹ̀lé òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi àpèjúwe wọn lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn

[4] Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (lójú ogun ẹ̀sìn), ẹ máa bẹ́ wọn lọ́rùn ǹsó títí di ìgbà tí ẹ máa fi borí wọn. (Tí ẹ bá ṣẹ́gun) kí ẹ dè wọ́n nígbèkùn. Lẹ́yìn náà, ẹ lè tú wọn sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ títí (okùnfà) ogun ẹ̀sìn yóò fi kásẹ̀ nílẹ̀. Ìyẹn (wà bẹ́ẹ̀). Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá gbẹ̀san fúnra Rẹ̀ (láì níí la ogun jíjà lọ), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dán apá kan yín wò lára apá kan ni. Àwọn mùsùlùmí tí wọ́n sì pa sí ojú ogun ẹ̀sìn, Allāhu kò níí sọ iṣẹ́ wọn dòfò

[5] Ó máa tọ́ wọn sọ́nà. Ó sì máa tún ọ̀rọ̀ wọn ṣe sí dáadáa

[6] Ó máa fi wọ́n wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí Ó ti fi mọ̀ wọ́n

[7] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá ran (ẹ̀sìn) Allāhu lọ́wọ́, (Allāhu) máa ràn yín lọ́wọ́. Ó sì máa mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin

[8] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, ègbé ni fún wọn. (Allāhu) sì máa ba iṣẹ́ wọn jẹ́

[9] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, (Allāhu) sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́

[10] Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Allāhu pa wọ́n rẹ́. Irú rẹ̀ tún wà fún àwọn aláìgbàgbọ́

[11] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn

[12] Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn ń gbádùn, wọ́n sì ń jẹ (kiri) gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹran-ọ̀sìn ṣe ń jẹ (kiri). Iná sì ni ibùgbé fún wọn

[13] Mélòó mélòó nínú àwọn (ará) ìlú tí ó lágbára ju (ará) ìlú rẹ, tí ó lé ọ jáde, tí A sì ti pa wọ́n rẹ́. Kò sì sí alárànṣe kan fún wọn

[14] Ǹjẹ́ ẹni tí ó wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, ṣé ó dà bí ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn

[15] Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí Wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (nìyí): àwọn omi odò wà nínú rẹ̀ tí kò níí yí padà àti àwọn odò wàrà tí adùn rẹ̀ kò níí yí padà àti àwọn odò ọtí dídùn fún àwọn t’ó máa mu ún àti àwọn odò oyin mímọ́. Àwọn onírúurú èso wà fún wọn nínú rẹ̀ àti àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. (Ṣé ẹni tí ó wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra yìí) dà bí olùṣegbére nínú Iná bí, tí wọ́n ń fún wọn ní omi gbígbóná mu, tí ó sì máa já àwọn ìfun wọn pútupùtu

[16] Ó wà nínú wọn, ẹni tí ó tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ títí di ìgbà tí wọ́n bá jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ tán, wọn yó sì wí fún àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pé: "Kí l’ó sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀ kan ná?" Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti dí ọkàn wọn pa. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn

[17] Àwọn t’ó sì tẹ̀lé ìmọ̀nà, (Allāhu) ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn. Ó sì máa fún wọn ní ìbẹ̀rù wọn (nínú Allāhu)

[18] Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà, tí ó máa dé bá wọn ní òjijì? Àwọn àmì rẹ̀ kúkú ti dé. Nítorí náà, báwo ni ìrántí (yó ṣe wúlò fún) wọ́n nígbà tí ó bá dé bá wọn

[19] Nítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu. Kí o sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu mọ lílọ-bíbọ̀ yín àti ibùsinmi yín

[20] Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo ń sọ pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ sūrah kan kalẹ̀?" Nígbà tí wọ́n bá sọ sūrah aláìnípọ́n-na kalẹ̀, tí wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ ìjà ogun ẹ̀sìn nínú rẹ̀, ìwọ yóò rí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa wò ọ́ ní wíwò bí ẹni pé wọ́n ti dákú lọ pọnrangandan. Ohun tí ó sì dára jùlọ fún wọn

[21] ni ìtẹ̀lé àṣẹ (Allāhu) àti (sísọ) ọ̀rọ̀ rere. Nígbà tí ogun ẹ̀sìn sì ti di dandan, wọn ìbá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ìbá dára jùlọ fún wọn

[22] Ǹjẹ́ kò súnmọ́ tí ẹ̀yin (aláìsàn ọkàn wọ̀nyí) bá dé’pò àṣẹ, pé ẹ ò níí ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti pé ẹ ò níí já okùn-ìbí yín

[23] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣẹ́bi lé. Nítorí náà, Ó di wọ́n létí pa. Ó sì fọ́ ìríran wọn

[24] Ṣé wọn kò níí ronú nípa al-Ƙur’ān ni tàbí àwọn àgádágodo ti wà lórí ọkàn wọn ni

[25] Dájúdájú àwọn t’ó pẹ̀yìn dà (sí ’Islām) lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, Èṣù ló ṣe ìṣìnà ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì fún wọn ní ìrètí asán nípa ẹ̀mí gígùn

[26] Ìyẹn nítorí pé (àwọn aláìsàn ọkàn) ń sọ fún àwọn t’ó kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ pé: "Àwa yóò tẹ̀lé yin nínú apá kan ọ̀rọ̀ náà." Allāhu sì mọ àṣírí wọn

[27] Báwo ni (ó ṣe máa rí) nígbà tí àwọn mọlāika bá gba ẹ̀mí wọn, tí wọn yó sì máa gbá ojú wọn àti ẹ̀yìn wọn

[28] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n tẹ̀lé ohun tí ó bí Allāhu nínú. Wọ́n sì tún kórira ìyọ́nú Rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu ti ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́

[29] Tàbí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn ń lérò pé Allāhu kò níí ṣe àfihàn àdìsọ́kàn burúkú wọn ni

[30] Àti pé tí A bá fẹ́ Àwa ìbá fi wọ́n hàn ọ́, ìwọ ìbá sì mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Dájúdájú ìwọ yóò mọ̀ wọ́n nípa ìpẹ́kọrọ-sọ̀rọ̀ (wọn). Allāhu sì mọ àwọn iṣẹ́ (ọwọ́) yín

[31] Dájúdájú A máa dan yín wò títí A fi máa ṣàfi hàn àwọn olùjagun-ẹ̀sìn àti àwọn onísùúrù nínú yín. A sì máa gbìdánwò àwọn ìró yín

[32] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n tún kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, wọn kò lè kó ìnira kiní kan bá Allāhu. (Allāhu) yó sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́

[33] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ náà, kí ẹ sì má ṣe ba àwọn iṣẹ́ yín jẹ́

[34] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, lẹ́yìn náà tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, Allāhu kò níí foríjìn wọ́n

[35] Ẹ má ṣe káàárẹ̀, kí ẹ sì má ṣe pèpè fún kòsógunmọ́, nígbà tí ẹ bá ń lékè lọ́wọ́. Allāhu wà pẹ̀lú yín; kò sì níí kó àdínkù bá ẹ̀san àwọn iṣẹ́ yín

[36] Eré àti ìranù ni ìṣẹ̀mí ayé. (Àmọ́) tí ẹ bá gbàgbọ́ (nínú Allāhu), tí ẹ sì bẹ̀rù (Rẹ̀), Ó máa fun yín ní àwọn ẹ̀san yín. Kò sì níí bèèrè àwọn dúkìá yín (pé kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh)

[37] Tí (Allāhu) bá bèèrè rẹ̀ ní ọwọ́ yín (pé kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh), tí Ó sì won̄koko mọ yín, ẹ máa ṣahun. Ó sì máa mú àrùn ọkàn yín jadé (àṣírí yín yó sì tú síta)

[38] Ẹ̀yin náà mà nìwọ̀nyí tí wọ́n ń pè láti náwó fún ẹ̀sìn Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni t’ó ń ṣahun wà nínú yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣahun, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu ni Ọlọ́rọ̀. Ẹ̀yin sì ni aláìní. Tí ẹ bá gbúnrí, (Allāhu) máa fi ìjọ mìíràn pààrọ̀ yín. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dà bí irú yin

Ìṣẹ́gun

Surah 48

[1] Dájúdájú Àwa fún ọ ní ìṣẹ́gun pọ́nńbélé

[2] nítorí kí Allāhu lè ṣàforíjìn ohun tí ó ṣíwájú nínú àṣìṣe rẹ àti ohun tí ó kẹ́yìn (nínú rẹ̀), àti nítorí kí Ó lè ṣàṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ lé ọ lórí àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām)

[3] àti nítorí kí Allāhu lè ṣàrànṣe fún ọ ní àrànṣe t’ó lágbára

[4] Òun ni Ẹni tí Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ sínú ọkàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí wọ́n lè lékún ní ìgbàgbọ́ sí ìgbàgbọ́ wọn. Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[5] (Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn) nítorí kí Ó lè mú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ, olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀, àti nítorí kí Ó lè pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ èrèǹjẹ ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu

[6] Àti nítorí kí Ó lè fìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, pẹ̀lú àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin, àwọn eléròkérò nípa Allāhu ní ti èrò aburú. Àpadàsí aburú ń bẹ fún wọn. Allāhu ti bínú sí wọn. Ó ti ṣẹ́bi lé wọn. Ó sì ti pèsè iná Jahnamọ sílẹ̀ dè wọ́n. Ó sì burú ní ìkángun

[7] Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[8] Dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀

[9] nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti (nítorí kí) ẹ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún (Òjíṣẹ́ náà) àti nítorí kí ẹ lè pàtàkì rẹ̀, àti nítorí kí ẹ lè ṣàfọ̀mọ́ fún (Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́

[10] Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣàdéhùn fún ọ (pé àwọn kò níí fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun), dájúdájú Allāhu ni wọ́n ń ṣàdéhùn fún. Ọwọ́ Allāhu wà lókè ọwọ́ wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tú àdéhùn rẹ̀, ó tú u fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú àdéhùn t’ó ṣe fún Allāhu ṣẹ, (Allāhu) yóò fún un ní ẹ̀san ńlá

[11] Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn nínú àwọn Lárúbáwá oko yóò máa wí fún ọ pé: "Àwọn dúkìá wa àti àwọn ará ilé wa l’ó kó àìrójú bá wa. Nítorí náà, tọrọ àforíjìn fún wa." Wọ́n ń fi ahọ́n wọn wí ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Sọ pé: "Ta ni ó ní ìkápá kiní kan fun yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá gbèrò (láti fi) ìnira kàn yín tàbí tí Ó bá gbèrò àǹfààní kan fun yín? Rárá (kò sí). Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[12] Rárá (kì í ṣe iṣẹ́ kan l’ó di yín lọ́wọ́ láti lọ jagun, àmọ́) ẹ ti lérò pé Òjíṣẹ́ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò níí padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn mọ́ láéláé. Wọ́n ṣe ìyẹn ni ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ẹ sì ro èrò aburú. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ìparun

[13] Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ gbọ́, dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[14] Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[15] Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: "Nígbà tí ẹ lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kaebar) nítorí kí ẹ lè rí n̄ǹkan kó, wọ́n já wa jù sílẹ̀ kí á má lè tẹ̀lé yín lọ." (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni. (Ìwọ Ànábì) sọ pé: "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." Wọn yó sì tún wí pé: "Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni." Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀

[16] Sọ fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun nínú àwọn Lárúbáwá oko pé: "Wọ́n máa pè yín sí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ní agbára ogun jíjà. Ẹ máa jà wọ́n lógun tàbí kí wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (fún ’Islām). Tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ (yìí), Allāhu yóò fun yín ní ẹ̀san t’ó dára. Tí ẹ̀yin bá sì gbúnrí padà gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe gbúnrí ṣíwájú, (Allāhu) yó sì fi ìyà ẹlẹ́ta-eléro jẹ yín

[17] Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn (tí wọn kò bá lọ sójú ogun). Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbúnrí, Ó máa jẹ ẹ́ ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[18] Dájúdájú Allāhu ti yọ́nú sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n ń ṣàdéhùn fún ọ lábẹ́ igi (pé àwọn kò níí fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun). Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn wọn. Ó sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún wọn. Ó sì san wọ́n ní ẹ̀san ìṣẹ́gun t’ó súnmọ́

[19] àti àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí wọn yóò rí kó. Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[20] Àti pé Allāhu ṣàdéhùn àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí ẹ̀yin yóò rí kó fun yín. Ó sì tètè mú èyí wá fun yín. Ó tún kó àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ró fun yín nítorí kí ó lè jẹ́ àmì kan fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ yín rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām)

[21] Àti òmíràn tí ẹ ò lágbára lórí rẹ̀, (àmọ́ tí) Allāhu ti rọkiriká rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[22] Tí ó bá jẹ́ pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ gbógun dìde si yín ni, wọn ìbá pẹ̀yìn dà (láti ságun fun yín). Lẹ́yìn náà, wọn kò níí rí aláàbò tàbí alárànṣe kan

[23] Ìṣe Allāhu, èyí t’ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú (ni èyí). O ò sì níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu (lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀)

[24] Òun sì ni Ẹni tí Ó kó wọn lọ́wọ́ ró fun yín. Ó sì kó ẹ̀yin náà lọ́wọ́ ró fún wọn nínú ìlú Mọkkah lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti fi yín borí wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[25] Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ṣẹ yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram, tí wọ́n tún de ẹran ọrẹ mọ́lẹ̀ kí ó má lè dé àyè rẹ̀. Tí kì í bá ṣe ti àwọn ọkùnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn obìnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo (nínú ìlú Mọkkah), tí ẹ̀yin kò sì mọ̀ wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ pa wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ fara kó ẹ̀ṣẹ̀ láti ara wọn nípasẹ̀ àìmọ̀, (Allāhu ìbá tí ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn. Allāhu ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn sẹ́) nítorí kí Ó lè fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni (onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀, aláìgbàgbọ́ lọ́tọ̀), Àwa ìbá jẹ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[26] (Rántí) nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kó ìgbónára sínú ọkàn wọn ní ìgbónára ti ìgbà àìmọ̀kan, Allāhu sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rù (Rẹ̀) wà pẹ̀lú wọn; Wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí i jùlọ, àwọn ni wọ́n sì ni ín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[27] Dájúdájú Allāhu ti sọ àlá Òjíṣẹ́ Rẹ̀ di òdodo pé - tí Allāhu bá fẹ́ - dájúdájú ẹ̀yin yóò wọ inú Mọ́sálásí Haram ní ẹni ìfàyàbalẹ̀. Ẹ máa fá irun orí yín; ẹ máa gé irun (orí yín mọ́lẹ̀), ẹ ò sì níí páyà. Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Ó tún ṣe ìṣẹ́gun t’ó súnmọ́ (fun yín)

[28] (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí

[29] Muhammad ni Òjíṣẹ́ Allāhu. Àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́, aláàánú sì ni wọ́n láààrin ara wọn. O máa rí wọn ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun), tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Àmì wọn wà ní ojú wọn níbi orípa ìforíkanlẹ̀. Ìyẹn ni àpèjúwe wọn nínú Taorāh àti àpèjúwe wọn nínú ’Injīl, gẹ́gẹ́ bí kóró èso igi t’ó yọ ọ̀gọ́mọ̀ rẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, ó nípọn (ó lágbára), ó sì dúró gbagidi lórí igi rẹ̀. Ó sì ń jọ àwọn àgbẹ̀ lójú. (Allāhu fi àyè gba Ànábì àti àwọn Sọhābah rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi wọ́n ṣe ohun ìbínú fún àwọn aláìgbàgbọ́. Allāhu ṣàdéhùn àforíjìn àti ẹ̀san ńlá fún àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere nínú wọn

Àwọn Ìyàrá

Surah 49

[1] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ gbawájú mọ́ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀

[2] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe gbé ohùn yín ga borí ohùn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Kí ẹ sì má ṣe fi ohùn ariwo bá a sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan yín ṣe ń fi ohùn ariwo bá apá kan sọ̀rọ̀ nítorí kí àwọn iṣẹ́ yín má baà bàjẹ́, ẹ̀yin kò sì níí fura

[3] Dájúdájú àwọn t’ó ń rẹ ohùn wọn nílẹ̀ lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti gbìdánwò ọkàn wọn fún ìbẹ̀rù (Rẹ̀). Àforíjìn àti ẹ̀san ńlá wà fún wọn

[4] Dájúdájú àwọn t’ó ń pè ọ́ láti ẹ̀yìn àwọn yàrá, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè

[5] Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n ṣe sùúrù títí o máa fi jáde sí wọn ni, ìbá dára jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[6] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí òbìlẹ̀jẹ́ kan bá mú ìró kan wá ba yín, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti mọ òdodo (nípa ọ̀rọ̀ náà) nítorí kí ẹ má baà ṣe àwọn ènìyàn kan ní ṣùtá pẹ̀lú àìmọ̀. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má baà di alábàámọ̀ lórí ohun tí ẹ ṣe

[7] Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín. Tí ó bá jẹ́ pé ó ń tẹ̀lé yín níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ (t’ó ń ṣẹlẹ̀) ni, dájúdájú ẹ̀yin ìbá ti kó o sínú ìdààmú. Ṣùgbọ́n Allāhu jẹ́ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ òdodo. Ó ṣe é ní ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ó sì jẹ́ kí ẹ kórira àìgbàgbọ́, ìwà burúkú àti ìyapa àṣẹ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùmọ̀nà

[8] (Èyí jẹ́) oore àjùlọ àti ìdẹ̀ra láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[9] Tí igun méjì nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo bá ń bá ara wọn jà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì bá sì kọjá ẹnu-àlà lórí ìkejì, ẹ bá èyí tí ó kọjá ẹnu-àlà jà títí ó fi máa ṣẹ́rí padà síbi àṣẹ Allāhu. Tí ó bá sì ṣẹ́rí padà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú déédé. Kí ẹ sì ṣe ẹ̀tọ́. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-ẹ̀tọ́

[10] Ọmọ ìyá (ẹ̀sìn) ni àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹ ṣàtúnṣe láààrin àwọn ọmọ ìyá yín méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí A lè kẹ yín

[11] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn ènìyàn kan kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ènìyàn kan ṣe yẹ̀yẹ́. Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (t’ó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Àwọn obìnrin kan (kò sì gbọ́dọ̀ fi) àwọn obìnrin kan (ṣe yẹ̀yẹ́). Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (t’ó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹ má ṣe búra yín. Ẹ má pe’ra yín lóríkì burúkú lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú pìwàdà, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn alábòsí

[12] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jìnnà sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àròsọ. Dájúdájú apá kan àròsọ ni ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ má ṣe tọpinpin ara yín. Kí apá kan yín má ṣe sọ̀rọ̀ apá kan lẹ́yìn. Ṣé ọ̀kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí láti jẹ ẹran-ara ọmọ ìyá rẹ̀ t’ó ti kú ni? Ẹ sì kórira rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[13] Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán

[14] Àwọn Lárúbáwá oko sọ pé: "A gbàgbọ́ ní òdodo." Sọ pé: "Ẹ̀yin kò gbàgbọ́ ní òdodo." Ṣùgbọ́n ẹ sọ pé: "A gba ’Islām." níwọ̀n ìgbà tí ìgbàgbọ́ òdodo kò tí ì wọ’nú ọkàn yín. Tí ẹ bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) kò níí dín kiní kan kù fun yín nínú (ẹ̀san) àwọn iṣẹ́ yín. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[15] Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí wọn kò ṣeyèméjì, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olódodo

[16] Sọ pé: "Ṣé ẹ máa kọ́ Allāhu ní ẹ̀sìn yín ni?" Allāhu sì mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[17] Wọ́n ń ṣèrègún lórí rẹ pé wọ́n gba ’Islām. Sọ pé: "Ẹ má fi ’Islām yín ṣèrègún lórí mi.” Bẹ́ẹ̀ ni! Allāhu l’Ó máa ṣèrègún lórí yín pé Ó fi yín mọ̀nà síbi ìgbàgbọ́ òdodo tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[18] Dájúdájú Allāhu mọ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

Qāf

Surah 50

[1] Ƙọ̄f. (Allāhu fi) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé búra

[2] Ṣùgbọ́n wọ́n ṣèèmọ̀ nítorí pé olùkìlọ̀ kan wá bá wọn láti ààrin ara wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ sì wí pé: "Èyí ni ohun ìyanu

[3] Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ (ni a óò tún jí dìde padà). Ìyẹn ni ìdápadà tó jìnnà (sí n̄ǹkan tí ó lè ṣẹlẹ̀)

[4] Dájúdájú A ti mọ ohun tí ilẹ̀ ń mú jẹ nínú wọn. Tírà (iṣẹ́ ẹ̀dá ) tí wọ́n ń ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ Wa

[5] Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe òdodo (al-Ƙur’ān) ní irọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, wọ́n ti wà nínú ìdààmú

[6] Ṣé wọn kò wo sánmọ̀ òkè wọn bí A ti ṣe mọ ọ́n pa àti (bí) A ti ṣe é ní ọ̀ṣọ́, tí kò sì sí àlàfo sísán kan lára rẹ̀

[7] Àti pé ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú oríṣiríṣi irúgbìn t’ó dára hù jáde láti inú rẹ̀

[8] (Ó jẹ́) àríwòye àti ìrántí fún gbogbo ẹrúsìn tó ń ṣẹ́rí padà (síbi òdodo)

[9] A ń sọ omi ìbùkún kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì ń fi mú àwọn ọgbà oko àti àwọn èso tí wọ́n máa kájẹ hù jáde

[10] (A tún mú) igi dàbínù hù ga, tí àwọn èso orí rẹ̀ so jìgbìnnì

[11] Arísìkí ni fún àwọn ẹrú (Allāhu). A sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè. Báyẹn ni ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè yó ṣe rí)

[12] Àwọn ènìyàn (Ànábì) Nūh, àwọn ènìyàn Rass àti àwọn (ènìyàn) Thamūd pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn

[13] Àti àwọn ‘Ād, Fir‘aon àti àwọn ọmọ ìyá (Ànábì) Lūt

[14] àti àwọn ará ’Aekah àti àwọn ìjọ Tubba‘u; gbogbo wọn pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìlérí Mi sì di ẹ̀tọ́ (lórí wọn)

[15] Ǹjẹ́ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ kó agara bá Wa bí? Rárá, wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìṣẹ̀dá (wọn) ní titun ni

[16] Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn. A sì mọ ohun tí ẹ̀mí rẹ̀ ń sọ fún un. Àwa sì súnmọ́ ọn ju isan ọrùn rẹ̀

[17] (Rántí) nígbà tí (mọlāika) àwọn agbọ̀rọ̀-sílẹ̀ méjì bá bẹ̀rẹ̀sí gba ọ̀rọ̀ (sílẹ̀), tí ọ̀kan jókòó sí ọ̀tún, tí ọ̀kan jókòó sí òsì

[18] (Ẹnì kan) kò sì níí sọ ọ̀rọ̀ kan àyàfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà pẹ̀lú rẹ̀ (fún àkọsílẹ̀ rẹ̀)

[19] Àti pé ìpọ́kàkà ikú yóò dé láti fi òdodo ọ̀run rinlẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí ìwọ ń sá fún

[20] Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ìyẹn ni ọjọ́ ìlérí náà

[21] Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò wá pẹ̀lú olùdarí kan àti ẹlẹ́rìí kan (nínú àwọn mọlāika)

[22] Dájúdájú ìwọ ti wà nínú ìgbàgbéra níbi èyí. A sì ti ṣí èbìbò (ojú) rẹ kúrò fún ọ báyìí. Nítorí náà, ìríran rẹ yóò ríran kedere ní òní

[23] (Mọlāika) alábàárìn rẹ̀ yóò sọ pé: "Èyí ni ohun tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi (gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀)

[24] Ẹ jù ú sínú iná Jahanamọ, gbogbo aláìgbàgbọ́ olóríkunkun

[25] olùdènà-iṣẹ́ rere, alákọyọ, oníyèméjì

[26] ẹni tó mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Ẹ jù ú sínú ìyà líle

[27] (Èṣù) alábàárìn rẹ̀ yóò wí pé: "Olúwa wa, èmi kọ́ ni mo ṣì í lọ́nà, ṣùgbọ́n ó ti wà nínú ìṣìnà tó jìnnà (sí òdodo) tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀

[28] (Allāhu) yóò sọ pé: "Ẹ má se ṣàríyànjiyàn lọ́dọ̀ Mi. Mo kúkú ti ṣe ìlérí fun yín ṣíwájú

[29] Wọn kò sì lè yí ọ̀rọ̀ náà padà ní ọ̀dọ̀ Mi. Èmi kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrú Mi

[30] (Rántí) ọjọ́ tí A óò sọ fún iná Jahnamọ pé: Ṣèbí o ti kún?" Ó sì máa sọ pé: "Ṣèbí àfikún tún wà

[31] Wọ́n máa sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). Kò sì níí jìnnà (sí wọn)

[32] Èyí ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún gbogbo olùronúpìwàdà, olùṣọ́ (òfin Allāhu)

[33] Ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Allāhu ní ìkọ̀kọ̀, tí ó tún dé pẹ̀lú ọkàn tó ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà)

[34] (A óò sọ fún wọn pé:) "Ẹ wọ inú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àlàáfíà. Ìyẹn ni ọjọ́ gbére

[35] Ohun tí wọ́n ń fẹ́ wà nínú rẹ̀. Àlékún sì tún wà ní ọ̀dọ̀ Wa

[36] Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Wọ́n sì ní agbára jù wọ́n lọ. (Nígbà tí ìyà dé) wọ́n sá àsálà kiri nínú ìlú. Ǹjẹ́ ibùsásí kan wà (fún wọn bí)

[37] Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ní ọkàn tàbí ẹni tó fi etí sílẹ̀, tó wà níbẹ̀ (pẹ̀lú ọkàn rẹ̀)

[38] Dájúdájú A ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà. Kò sì rẹ̀ Wá rárá (áḿbọ̀sìbọ́sí pé A óò sinmi ní ọjọ́ keje)

[39] Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀)

[40] Àti pé ní òru àti ni ẹ̀yìn ìrun ṣe àfọ̀mọ́ fún Un

[41] Kí o sì tẹ́tí sí ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè láti àyè kan t’ó súnmọ́

[42] Ọjọ́ tí wọn yóò gbọ́ igbe pẹ̀lú òdodo. Ìyẹn ni ọjọ́ ìjáde ẹ̀dá (láti inú sàréè)

[43] Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ ẹ̀dá di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[44] (Rántí) ọjọ́ tí ilẹ̀ yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ mọ́ wọn lára, (tí wọn yóò máa) yára (jáde láti inú ilẹ̀). Ìyẹn ni àkójọ t’ó rọrùn fún Wa

[45] Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí. Ìwọ kò sì níí jẹ wọ́n nípá (láti gbàgbọ́). Nítorí náà, fi al-Ƙur’ān ṣe ìrántí fún ẹni tí ń páyà ìlérí Mi

Àwọn Afẹ́fẹ́ Tí ń fẹ́

Surah 51

[1] (Allāhu búra pẹ̀lú) atẹ́gùn t’ó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ tààrà

[2] (Ó búra pẹ̀lú) àwọn ẹ̀ṣújò t’ó wúwo rinrin

[3] (Ó búra pẹ̀lú) àwọn ọkọ̀ ojú-omi t’ó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn

[4] (Ó búra pẹ̀lú) àwọn mọlāika t’ó ń pín n̄ǹkan (tí Ó ti pín fún ẹ̀dá)

[5] Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín

[6] Àti pé dájúdájú Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀

[7] (Allāhu tún búra pẹ̀lú) sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́

[8] Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ t’ó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān)

[9] Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ)

[10] Ègbé ni fún àwọn òpùrọ́

[11] àwọn ni wọ́n wà nínú àìmọ̀kan, àwọn onígbàgbé

[12] tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀

[13] Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà

[14] Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú

[15] Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀)

[16] Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn

[17] Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru

[18] Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́

[19] Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún

[20] Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú

[21] Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ ò ríran ni

[22] Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fun yín wà nínú sánmọ̀

[23] Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀

[24] Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ

[25] (Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: "Àlàáfíà (fún ọ)." Òun náà sọ pé: "Àlàáfíà (fun yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn

[26] Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù ọlọ́ràá (àyangbẹ)

[27] Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí jẹun ni

[28] Nígbà náà, ó ní ìpáyà wọn nínú ọkàn. Wọ́n sọ pé: "Má ṣe páyà." Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin onímọ̀ kan

[29] Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: "Arúgbó, àgàn (mà ni mí)

[30] Wọ́n sọ pé: "Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀

[31] (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́

[32] Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni

[33] nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn

[34] Wọ́n ti fàmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ

[35] Nítorí náà, A mú àwọn t’ó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà)

[36] A ò sì rí nínú (ìlú náà) tayọ ilé kan t’ó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí

[37] A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn t’ó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[38] (Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon

[39] Ṣùgbọ́n (Fir‘aon) gbúnrí pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó sì wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí)

[40] Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù

[41] (Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn

[42] kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kó sọ ọ́ di bí èso rírún túútú

[43] (Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: "Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná

[44] Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, igbe ìparun mú wọ́n; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀

[45] Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́

[46] Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò

[47] Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni olùgbòòrò

[48] Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. Àwọn olùtẹ́lẹ̀-sílẹ̀ sì dára

[49] Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí

[50] Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[51] Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[52] Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn t’ó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: "Òpìdán tàbí wèrè ni

[53] Ṣé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-àlà ni wọ́n ni

[54] Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe alábùkù

[55] Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[56] Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi

[57] Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi

[58] Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle

[59] Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn t’ó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn)

[60] Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

Òkè

Surah 52

[1] (Allāhu búra pẹ̀lú) àpáta Tūr

[2] (Ó tún búra pẹ̀lú) Tírà tí wọ́n kọ sílẹ̀

[3] sínú tákàdá tí wọ́n tẹ́ sílẹ̀

[4] (Ó tún búra pẹ̀lú) Ilé Àbẹ̀wò náà

[5] (Ó tún búra pẹ̀lú) àjà tí wọ́n gbé sókè (ìyẹn, sánmọ̀)

[6] (Ó tún búra pẹ̀lú) agbami odò iná

[7] Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ máa ṣẹlẹ̀

[8] Kò sí olùdènà kan fún un

[9] (Ó máa ṣẹlẹ̀) ní ọjọ́ tí sánmọ̀ máa mì tìtì tààrà

[10] Àwọn àpáta sì máa rìn lọ tààrà (bí eruku àfẹ́dànù)

[11] Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[12] àwọn tí wọ́n wà nínú ìsọkúsọ, tí wọ́n ń ṣeré

[13] (Rántí) ọjọ́ tí wọn yóò tì wọ́n lọ́ sínú iná Jahanamọ ní ìtìkutì

[14] Èyí ni Iná náà tí ẹ̀ ń pè nírọ́

[15] Ṣé idán ni èyí ni tàbí ẹ ò ríran

[16] Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ. Ẹ fara dà á tàbí ẹ ò fara dà á, bákan náà ni fun yín. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san

[17] Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà àti ìdẹ̀ra

[18] Wọn yóò máa jẹ ìgbádùn pẹ̀lú ohun tí Olúwa wọn fún wọn. Àti pé (Allāhu) yóò ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm

[19] Ẹ máa jẹ, ẹ máa mu ní gbẹdẹmukẹ nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[20] Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. A sì máa fún wọn ní àwọn ìyàwó ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́

[21] Àti pé àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn tún tẹ̀lé wọn nínú ìgbàgbọ́ òdodo, A máa da àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn pọ̀ mọ́ wọn. A ò sì níí dín kiní kan kù nínú iṣẹ́ wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́

[22] A máa fún wọn ní àlékún èso àti ẹran tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí

[23] Wọn yó sì máa gba ife ọtí mu láààrin ara wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò sí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra

[24] Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. (Wọ́n) dà bí àlúùúlù àfipamọ́

[25] Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, wọn yó sì máa bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ara wọn

[26] Wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwa jẹ́ olùpáyà láààrin àwọn ènìyàn wa

[27] Ṣùgbọ́n Allāhu ṣàánú wa. Ó sì là wá níbi ìyà Iná

[28] Dájúdájú àwa máa ń pè É tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olóore, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[29] Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kì í ṣe adábigba tàbí wèrè lórí ìdẹ̀ra Olúwa rẹ

[30] Tàbí wọ́n ń wí pé: "Eléwì kan tí à ń retí ikú rẹ̀ ni

[31] Sọ pé: "Ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí

[32] Tàbí ọpọlọ wọn ń pa wọ́n láṣẹ èyí ni? Tàbí ìjọ alákọyọ ni wọ́n ni

[33] Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni." Rárá o, wọn kò gbàgbọ́ ni

[34] Kí àwọn náà mú ọ̀rọ̀ kan bí irú rẹ̀ wá tí wọ́n bá jẹ́ olódodo

[35] Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni

[36] Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni

[37] Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn àpótí ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí

[38] Tàbí wọ́n ní àkàbà tí wọ́n ń fi gbọ́rọ̀ (nínú sánmọ̀ ni)? Kí olùgbọ́rọ̀ wọn mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá

[39] Tàbí àwọn ọmọbìnrin ni tiRẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì ni tiyín

[40] Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́dọ̀ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn

[41] Tàbí ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sílẹ̀

[42] Tàbí wọ́n ń gbèrò ète kan ni? Nígbà náà, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn l’ó máa f’orí kó ète

[43] Tàbí wọ́n ní ọlọ́hun kan lẹ́yìn Allāhu ni? Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I

[44] Tí wọ́n bá sì rí apá kan nínú sánmọ̀ t’ó ya lúlẹ̀, wọ́n á wí pé: "Ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ ni (wọn kò níí gbàgbọ́)

[45] Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ títí wọn yóò fi bá ọjọ́ wọn tí wọn máa pa wọ́n sínú rẹ̀ pàdé

[46] Ọjọ́ tí ète wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́

[47] Àti pé dájúdájú ìyà kan ń bẹ fún àwọn t’ó ṣàbòsí yàtọ̀ sí (ìyà ọ̀run) yẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀

[48] Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ nígbà tí ó bá ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)

[49] Àti ní alẹ́ (nígbà tí) àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán, ṣàfọ̀mọ́ fún Un

Ìràwọ̀

Surah 53

[1] (Allāhu búra pẹ̀lú) ìràwọ̀ nígbà tí ó bá jábọ́

[2] Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù

[3] Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú

[4] Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i

[5] Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān)

[6] Ó ní àlàáfíà t’ó péye. Nítorí náà, ó dúró wámúwámú

[7] nígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá

[8] Lẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá)

[9] (Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn)

[10] Allāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí t’Ó fún un

[11] Ọkàn (Ànábì) kò parọ́ ohun t’ó rí

[12] Ṣé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun t’ó rí ni

[13] Àti pé dájúdájú ó rí i nígbà kejì Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni ó rí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu bíi ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu) wá pé “Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi ọkàn rẹ̀ rí Allāhu ni.” Ìyẹn ni pé

[14] níbi igi sidirah al-Muntahā

[15] nítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà

[16] (Rántí) nígbà tí ohun t’ó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀

[17] Ojú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-àlà

[18] Dájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, t’ó tóbi jùlọ

[19] Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā

[20] àti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn

[21] Ṣé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀

[22] Ìpín àbòsí nìyẹn nígbà náà

[23] (Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fi sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́. Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn

[24] Tàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan t’ó bá ń fẹ́

[25] Ti Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé

[26] Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí

[27] Dájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin

[28] Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àròsọ kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo

[29] Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni t’ó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé

[30] Ìyẹn ni òdíwọ̀n (àti òpin) ìmọ̀ wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó mọ̀nà

[31] Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere

[32] Àwọn t’ó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́. Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀)

[33] Sọ fún mi nípa ẹni t’ó gbúnrí (kúrò níbi òdodo)

[34] tí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́

[35] Ṣé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run)

[36] Tàbí wọn kò fún un ní ìró ohun t’ó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni

[37] àti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni t’ó mú (òfin Allāhu) ṣẹ

[38] pé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn

[39] Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun t’ó ṣe níṣẹ́

[40] Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án

[41] Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san t’ó kún jùlọ

[42] Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá)

[43] Dájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún

[44] Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè

[45] Dájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin

[46] láti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́

[47] Dájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde

[48] Dájúdájú Òun l’Ó ń ṣe púpọ̀, Ó sì ń ṣe kékeré (oore fún ẹ̀dá)

[49] Dájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà)

[50] Dájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́

[51] àti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù

[52] àti ìjọ Nūh t’ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-àlà jùlọ

[53] àti ìlú tí wọ́n dàwó (ìlú Ànábì Lūt) t’Ó yẹ̀ lulẹ̀ (láti òkè)

[54] Ohun t’ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀

[55] Nítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn

[56] Èyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́

[57] Ohun t’ó súnmọ́ súnmọ́

[58] Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni t’ó lè ṣàfi hàn (Àkókò náà)

[59] Ṣé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì

[60] Ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ ò sì sunkún

[61] Afọ́nú-fọ́ra ni yín

[62] Nítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un)

Òṣùpá

Surah 54

[1] Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì)

[2] Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: "Idán kan (t’ó lágbára) t’ó máa lọ ni

[3] Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn

[4] Dájúdájú èyí tí wọ́n fi ohùn líle kọ̀ wà nínú àwọn ìró t’ó dé bá wọn

[5] Ìjìnlẹ̀ òye t’ó péye ni; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀

[6] Ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde)

[7] Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n

[8] Wọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Èyí ni ọjọ́ ìṣòro

[9] Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: "Wèrè ni." Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle. wọ́n fi ohùn líle kọ òdodo sílẹ̀ fún Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní kíkọ̀ àlésá-sẹ́yìn fún wọn nípasẹ̀ sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i híhalẹ̀ mọ̀ ọn

[10] Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Ràn mí lọ́wọ́

[11] Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi t’ó lágbára

[12] A tún mú àwọn odò ṣẹyọ lórí ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí)

[13] A sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó

[14] t’ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san fún ẹni tí wọ́n takò

[15] Dájúdájú A fi sílẹ̀ ní àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí

[16] Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)

[17] Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí

[18] Ìran ‘Ād pé òdodo nírọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)

[19] Dájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan t’ó ń tẹ̀ síwájú

[20] Ó ń fa àwọn ènìyàn jáde bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n

[21] Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)

[22] Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí

[23] Ìjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ nírọ́

[24] Wọ́n wí pé: "Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti ìyà

[25] Ṣé òun ni wọ́n sọ ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni

[26] Ní ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga

[27] Dájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù

[28] Kí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò

[29] Nígbà náà ni wọ́n pe ẹni wọn. Ó wá ọ̀nà láti mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á

[30] Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)

[31] Dájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí igi koríko gbígbẹ

[32] Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí

[33] Ìjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ nírọ́

[34] Dájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì

[35] (Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni t’ó bá dúpẹ́ (fún Wa)

[36] Ó kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn

[37] Wọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò

[38] Àti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù

[39] Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò

[40] Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí

[41] Dájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon

[42] Wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́, gbogbo rẹ̀ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (ń gbá ẹ̀dá mú)

[43] Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore jùlọ sí àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)

[44] Tàbí wọ́n ń wí pé: "Gbogbo wa ni a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)

[45] A máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun

[46] Àmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ

[47] Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà (nílé ayé, wọn yó sì wà nínú) Iná jíjò (ní ọ̀run)

[48] Ní ọjọ́ tí A óò dojú wọn délẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò

[49] Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá

[50] Àṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú

[51] Àti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí

[52] Gbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà

[53] Àti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀

[54] Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (t’ó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀)

[55] Ní ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá

Oloore Ọ̀fẹ́

Surah 55

[1] Àjọkẹ́-ayé

[2] Ó fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́)

[3] Ó ṣẹ̀dá ènìyàn

[4] Ó sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n

[5] Òòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé)

[6] Àwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu)

[7] Àti sánmọ̀, Allāhu gbé e sókè. Ó sì fi òṣùwọ̀n òfin déédé lélẹ̀ (fún ẹ̀dá)

[8] pé kí ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà níbi òṣùwọ̀n

[9] Ẹ gbé òṣùwọ̀n náà dúró pẹ̀lú dọ́gbadọ́gba. Kí ẹ sì má ṣe dín òṣùwọ̀n kù

[10] Ilẹ̀, (Allāhu) tẹ́ ẹ sílẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá

[11] Èso àti dàbínù alápó wà lórí (ilẹ̀)

[12] Àti èso kóró onípòpórò àti eléwé dúdú (wà lórí ilẹ̀)

[13] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[14] (Allāhu) ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ gbígbẹ t’ó ń dún kokoko bí ìkòkò amọ̀

[15] Ó sì ṣẹ̀dá àlùjànnú láti ara ahọ́n iná tí kò ní èéfín

[16] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[17] Olúwa ibùyọ òòrùn méjèèjì àti ibùwọ̀ òòrùn méjèèjì

[18] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[19] (Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn

[20] Gàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-àlà (rẹ̀ láààrin ara wọn)

[21] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[22] Òkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà

[23] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[24] Ti (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro t’ó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga

[25] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[26] Gbogbo ẹni t’ó wà lórí ilẹ̀ máa tán

[27] Ojú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé

[28] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[29] Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́

[30] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[31] A óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú

[32] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[33] Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ ò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára

[34] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[35] Wọ́n máa ju ẹ̀ta-pàrà iná àti ẹ̀ta-pàrà idẹ lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì lè ran’ra yín lọ́wọ́

[36] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[37] Nítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa

[38] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[39] Nítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn ò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa)

[40] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[41] Wọ́n máa mọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú

[42] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[43] Èyí ni iná Jahanamọ tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń pè nírọ́

[44] Wọn yóò máa rìn lọ rìn bọ̀ láààrin Iná àti omi t’ó gbóná parí

[45] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[46] Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì ń bẹ fún ẹni t’ó bá páyà ìdúró rẹ̀ níwájú Olúwa rẹ̀

[47] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[48] (Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra méjèèjì ní) àwọn ẹ̀ka igi gígùn

[49] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[50] Odò méjì t’ó ń ṣàn wà nínú ọgbà méjèèjì

[51] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[52] Oríṣi méjì méjì ni èso kọ̀ọ̀kan t’ó wà nínú ọgbà méjèèjì

[53] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[54] Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí ìtẹ́, tí àwọn ìtẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ àrán t’ó nípọn. Àwọn èso ọgbà méjèèjì sì wà ní àrọ́wọ́tó

[55] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[56] Àwọn obìnrin tí kì í wo ọkùnrin mìíràn wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò sì fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn

[57] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[58] Wọ́n dà bíi ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ̀gi àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn

[59] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[60] Ǹjẹ́ ẹ̀san mìíràn wà fún ṣíṣe rere bí kò ṣe (ẹ̀san) rere

[61] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[62] Ọgbà méjì kan tún ń bẹ yàtọ̀ sí méjì (àkọ́kọ́ yẹn)

[63] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[64] Aláwọ̀ ewéko (ni Ọgbà méjèèjì náà)

[65] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[66] Àwọn odò méjì t’ó ń tú omi jáde láì dáwọ́ dúró wà (nínú ọgbà méjèèjì náà)

[67] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[68] Èso ìpanu, dàbínù àti èso rumọ̄n wà nínú ọgbà méjèèjì

[69] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[70] Àwọn obìnrin rere, arẹwà wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

[71] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[72] Àwọn ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan (ni wọ́n), tí A fi pamọ́ sínú ilé-ọ̀ṣọ́

[73] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[74] Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn

[75] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[76] Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn tìmùtìmù aláwọ̀ ewéko àti ìtẹ́ t’ó dára

[77] Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́

[78] Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé

Dídájú

Surah 56

[1] Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀

[2] kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-E

[3] ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra)

[4] Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì

[5] àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú

[6] wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù - E

[7] ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta

[8] ìjọ òsì àti ìjọ aṣíwájú. Àmọ́ nínú sūrah al-Balad; 90:18-19 àti sūrah az-Zalzalah; 99:6-8 Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pín wọn sí ìjọ méjì. Ìjọ méjì kúkú ni gbogbo ẹ̀dá ní ọ̀run 8 Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

[9] Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì

[10] Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú

[11] Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)

[12] nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra

[13] Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́

[14] Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn

[15] (Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun

[16] Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn

[17] Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn

[18] pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn

[19] Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà

[20] Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn)

[21] Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn)

[22] Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn)

[23] Wọ́n dà bí òkúta olówó-iyebíye tí wọ́n fi pamọ́

[24] (Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́

[25] Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra

[26] Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà

[27] Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún

[28] (Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún

[29] àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ t’ó so jìgbìnnì

[30] àti ibòji t’ó gbòòrò

[31] àti omi t’ó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró

[32] àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso

[33] tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn)

[34] (Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè

[35] Dájúdájú Àwa tún (àwọn obìnrin wọn) dá ní ẹ̀dá ọ̀tun

[36] A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá

[37] olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí

[38] (Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

[39] Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́

[40] Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn

[41] Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì

[42] (Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná àti omi gbígbóná

[43] àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú

[44] kò tutù, kò sì dára

[45] Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn

[46] Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá

[47] Wọ́n sì máa ń wí pé: "Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni

[48] Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́

[49] Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn

[50] dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀

[51] Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́

[52] dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ)

[53] Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà

[54] Ẹ̀yin yó sì máa mu omi gbígbóná lé e lórí

[55] Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ

[56] Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san

[57] Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ lódodo

[58] Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́)

[59] ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀

[60] Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Àwa kò sì lè kágara

[61] láti fi irú yín pààrọ̀ yín, kí á sì tun yín dá sínú ohun tí ẹ kò mọ̀

[62] Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́, ẹ ò ṣe lo ìrántí

[63] Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀

[64] ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde ni tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde

[65] Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀)

[66] (Ẹ̀yin yó sì wí pé:) "Dájúdájú àwa ti di onígbèsè

[67] (Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) "Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni

[68] Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu

[69] ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀

[70] Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi t’ó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́

[71] Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá

[72] ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá

[73] Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò

[74] Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi

[75] Mò ń búra pẹ̀lú àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀

[76] Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀

[77] Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé

[78] (t’ó wà) nínú Tírà ààbò (nínú Laohul-Mahfūṭḥ)

[79] Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika)

[80] Wọ́n sọ̀ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[81] Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè nírọ́

[82] Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo nírọ́

[83] Kí ni ó máa ti rí (fun yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun

[84] tí ẹ̀yin yó sì máa wòran nígbà yẹn

[85] Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran

[86] Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀

[87] kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[88] Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa)

[89] ìsinmi, èsè t’ó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀)

[90] Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

[91] àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

[92] Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà

[93] n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi gbígbóná

[94] àti wíwọ inú iná Jẹhīm

[95] Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo t’ó dájú

[96] Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi

Irìn

Surah 57

[1] Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[2] TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Òun ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[3] Òun ni Àkọ́kọ́ àti Ìkẹ́yìn. Ó hàn (pẹ̀lú àmì bíbẹ Rẹ̀). Ó sì pamọ́ (fún gbogbo ojú nílé ayé). Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[4] Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó mọ n̄ǹkan t’ó ń wọ inú ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń jáde láti inú rẹ̀, àti n̄ǹkan t’ó ń sọ̀kalẹ̀ láti inú sánmọ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń gùnkè sínú rẹ̀. Àti pé Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[5] TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí

[6] Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Òun sì ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[7] Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kí ẹ sì ná nínú ohun tí Ó fi yín ṣe àrólé lórí rẹ̀. Nítorí náà, àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì náwó (sí ojú ọ̀nà ẹ̀sìn), ẹ̀san t’ó tóbi wà fún wọn

[8] Kí ni ó mu yín tí ẹ̀yin kò fi níí gba Allāhu gbọ́ ní òdodo? Òjíṣẹ́ sì ń pè yín nítorí kí ẹ lè gba Olúwa yín gbọ́. Allāhu sì ti gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo

[9] Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ àwọn āyah t’ó yanjú kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè mu yín kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fun yín

[10] Kí ni ó mu yín tí ẹ̀yin kò fi níí náwó fún ẹ̀sìn Allāhu? Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹni tí ó náwó ṣíwájú ṣíṣí ìlú Mọkkah, tí ó tún jagun ẹ̀sìn, kò dọ́gba láààrin yín (sí àwọn mìíràn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀san wọn tóbi jùlọ sí ti àwọn t’ó náwó lẹ́yìn ìgbà náà, tí wọ́n tún jagun ẹ̀sìn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni Allāhu ṣ’àdéhùn ẹ̀san rere fún. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[11] Ta ni ẹni tí ó máa yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára, Ó sì máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún un. Ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé sì tún wà fún un

[12] Ní ọjọ́ tí o máa rí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn níwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn, (A óò sọ pé:) "Ìró ìdùnnú yín ní òní ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀." Olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá

[13] Ní ọjọ́ tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin yóò wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Ẹ dúró fún wa ná, ẹ jẹ́ kí á mú nínú ìmọ́lẹ̀ yín." A óò sọ fún wọn pé: "Ẹ padà s’ẹ́yìn yín, kí ẹ lọ mú ìmọ́lẹ̀.” Wọ́n sì máa fi ògiri kan, t’ó ní ìlẹ̀kùn sáàrin wọn. Ìkẹ́ wà nínú rẹ̀, ìyà sì wà ní òde rẹ̀ ní ọwọ́ iwájú rẹ̀

[14] (Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò pe (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) pé: "Ṣé àwa kò ti wà pẹ̀lú yín ni?" Wọ́n sọ pé: "Rárá, ṣùgbọ́n ẹ kó ìyọnu bá ẹ̀mí ara yín (nípa ìṣọ̀bẹ-ṣèlu), ẹ retí ìparun (wá), ẹ sì ṣiyèméjì (sí òdodo). Àwọn ìfẹ́-ọkàn àti irọ́ ọ̀rọ̀ sì tàn yín jẹ títí àṣẹ Allāhu fi dé. Àti pé (Èṣù) ẹlẹ́tàn sì tàn yín jẹ nípa Allāhu

[15] Nítorí náà, ní òní Àwa kò níí gba ìtánràn kan ní ọwọ́ ẹ̀yin àti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Iná ni ibùgbé yín. Òhun l’ó tọ́ si yín. Ìkángun náà sì burú

[16] Ṣé àkókò kò tí ì tó fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé kí ọkàn wọn rọ̀ fún ìrántí Allāhu àti ohun t’ó sọ̀kalẹ̀ nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān). Kí wọ́n sì má ṣe dà bí àwọn tí A fún ní Tírà ní ìṣáájú; ìgbà pẹ́ lórí wọn, ọkàn wọn bá le. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́

[17] Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah náá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè

[18] Dájúdájú àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, tí wọ́n tún yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára, (Allāhu) yóò ṣàdìpèlé rẹ̀ fún wọn. Ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé sì wà fún wọn

[19] Àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olódodo àti ẹlẹ́rìí ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ẹ̀san wọn àti ìmọ́lẹ̀ wọn wà fún wọn. Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm

[20] Ẹ mọ̀ pé dájúdájú ìṣẹ̀mí ayé yìí jẹ́ eré, ìranù, ọ̀ṣọ́, ṣíṣe ìyanràn láààrin ara yín àti wíwá ọ̀pọ̀ dúkìá àti ọmọ. (Ìwọ̀nyí) dà bí òjò (t’ó mú irúgbìn jáde). Irúgbìn rẹ̀ sì ń jọ àwọn aláìgbàgbọ́ lójú. Lẹ́yìn náà, ó máa gbẹ. O sì máa rí i ní pípọ́n. Lẹ́yìn náà, ó máa di rírún (tí atẹ́gùn máa fẹ́ dànù). Ìyà líle àti àforíjìn pẹ̀lú ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu sì wà ní ọ̀run. Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn

[21] Ẹ yára lọ síbi àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra tí fífẹ̀ rẹ̀ dà bí fífẹ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀. Wọ́n pa á lésè sílẹ̀ de àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu tí Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore ńlá

[22] Àdánwò kan kò níí ṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ tàbí (kí ó ṣẹlẹ̀) sí ẹ̀yin àyàfi kí ó ti wà nínú Tírà ṣíwájú kí A t’ó dá ẹ̀dá. Dájúdájú ìyẹn rọ̀rùn fún Allāhu

[23] (Ìṣẹ̀lẹ̀ ń tọ kádàrá lẹ́yìn) nítorí kí ẹ má ṣe banújẹ́ lórí ohun tí ó bá bọ́ fun yín àti nítorí kí ẹ má ṣe yọ àyọ̀jù lórí ohun tí Ó bá fun yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo onígbèéraga, onífáàrí

[24] Àwọn t’ó ń ṣahun, tí wọ́n sì ń pa àwọn ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe (kí wọ́n mọ̀ pé) ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà (tí kò náwó fún ẹ̀sìn), dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́

[25] Dájúdájú A fi àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa. A sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn àti òṣùwọ̀n nítorí kí àwọn ènìyàn lè rí déédé ṣe (láààrin ara wọn). A tún sọ irin kalẹ̀. Ohun ìjagun t’ó lágbára àti àwọn àǹfààní wà nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni t’ó ń ran (ẹ̀sìn) Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí

[26] Dájúdájú A fi iṣẹ́ rán (Ànábì) Nūh àti (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. A fi ipò Ànábì sínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì pẹ̀lú Tírà (tí A fún wọn). Olùmọ̀nà wà nínú wọn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́

[27] Lẹ́yìn náà, A fi àwọn Òjíṣẹ́ Wa tẹ̀lé orípa wọn. A sì mú ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé wọn. A fún un ni al-’Injīl. A fi àánú àti ìkẹ́ sínú ọkàn àwọn t’ó tẹ̀lé e. Àṣà àdáwà (láì lọ́kọ tàbí láì laya) wọ́n ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀ ni. A ò ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí. (Wọn kò sì ṣe àdáwà fún kiní kan) bí kò ṣe láti fi wá ìyọ́nú Allāhu. Wọn kò sì rí i ṣọ́ bí ó ṣe yẹ kí wọ́n ṣọ́ ọ. Nítorí náà, A fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú wọn ní ẹ̀san wọn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́

[28] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gba Òjíṣẹ́ Rẹ̀ gbọ́ ní òdodo, nítorí kí (Allāhu) lè fun yín ní ìlọ́po méjì nínú ìkẹ́ Rẹ̀ àti nítorí kí Ó lè fun yín ní ìmọ́lẹ̀ tí ẹ óò máa fi rìn àti nítorí kí Ó lè forí jìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[29] (Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ fun yín) nítorí kí àwọn ahlu-l-kitāb lè mọ̀ pé àwọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú oore àjùlọ Allāhu. Àti pé dájúdájú oore àjùlọ, ọwọ́ Allāhu l’ó wà. Ó sì ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore ńlá

Obìnrin tí ń bẹ̀bẹ̀

Surah 58

[1] Dájúdájú Allāhu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ (obìnrin) t’ó ń bá ọ ṣe àríyànjiyàn nípa ọkọ rẹ̀, tí ó sì ń ṣàròyé fún Allāhu. Allāhu sì ń gbọ ìsọ̀rọ̀gbèsì ẹ̀yin méjèèjì. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran

[2] Àwọn t’ó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn nínú yín, àwọn ìyàwó kì í ṣe ìyá wọn. Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ìyá wọn bí kò ṣe ìyá tí ó bí wọn lọ́mọ. Dájúdájú wọ́n ń sọ aburú nínú ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ irọ́. Dájúdájú Allāhu ni Alámòójúkúrò, Aláforíjìn

[3] Àwọn t’ó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò níbi ohun tí wọ́n sọ, wọn máa tú ẹrú kan sílẹ̀ lóko ẹrú ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó lè súnmọ́ ara wọn. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fun yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[4] Ẹni tí kò bá rí (ẹrú), ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé ṣíwájú kí àwọn méjèèjì t’ó lè súnmọ́ ara wọn. Ẹni tí kò bá ní agbára (ààwẹ̀), ó máa bọ́ ọgọ́ta tálíkà. Ìyẹn nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbé kalẹ̀ fún ẹ̀dá. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́

[5] Dájúdájú àwọn t’ó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, A óò yẹpẹrẹ wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe yẹpẹrẹ àwọn t’ó ṣíwájú wọn. A kúkú ti sọ àwọn āyah t’ó yanjú kalẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́

[6] Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, àwọn sì gbàgbé rẹ̀. Allāhu sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan

[7] Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ni? Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn. Wọ́n kéré sí ìyẹn, wọ́n tún pọ̀ (ju ìyẹn) àfi kí Ó wà pẹ̀lú wọn ní ibikíbi tí wọ́n bá wà. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. āyah yìí kò túmọ̀ sí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà lórí ilẹ̀ ayé tàbí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan. Tí Allāhu bá ṣe ìkejì ẹnì kan tàbí Ó ṣe ìkẹta ẹni méjì bí kò ṣe pé wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ ni pé “Allāhu ń gbọ́ ohùn ẹ̀dá” nínú sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:85 ìsúnmọ́ tí Allāhu súnmọ́ ẹ̀dá ju bí a ṣe súnmọ́ ara wa lọ dúró fún bí àwọn mọlāika olùgbẹ̀mí-ẹ̀dá ṣe máa súnmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ní àkókò tí ẹ̀mí bá fẹ́ jáde lára ẹ̀dá. Èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 83 àti 84 nínú sūrah náà. Nítorí náà ìsúnmọ́ tí Allāhu ń tọ́ka sí nínú àwọn āyah wọ̀nyẹn àti irú wọn mìíràn kò túmọ̀ sí ìsọ̀kalẹ̀ Allāhu wá sí inú isan ọrùn ẹ̀dá

[8] Ṣé o ò rí àwọn tí A kọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ fún, lẹ́yìn náà tí wọ́n tún padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Wọ́n ń bára wọn sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Nígbà tí wọ́n bá sì dé ọ̀dọ̀ rẹ, wọn yóò kí ọ ní kíkí tí Allāhu kò fi kí ọ. Wọ́n sì ń wí sínú ẹ̀mí wọn pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Allāhu jẹ wá níyà lórí ohun tí à ń wí (ní ìkọ̀kọ̀)!" Iná Jahnamọ máa tó wọn. Wọ́n máa wọ inú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú

[9] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Ẹ bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[10] Dájúdájú ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (burúkú) ń wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù nítorí kí ó lè kó ìbànújẹ́ bá àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá wọn àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé

[11] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá sọ fun yín pé kí ẹ gbara yín láyè nínú àwọn ibùjókòó, ẹ gbara yín láyè. Allāhu yóò f’àyè gbà yín. Nígbà tí wọ́n bá sọ pé: "Ẹ dìde (síbi iṣẹ́ rere)." Ẹ dìde (sí i). Allāhu yóò ṣàgbéga àwọn ipò fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tí A fún ní ìmọ̀ nínú yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[12] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá bá Òjíṣẹ́ sọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ, ẹ fi ọrẹ títa ṣíwájú ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín. Ó sì fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Tí ẹ ò bá sì rí (ọrẹ), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[13] Ṣé ẹ̀ ń páyà (òṣì) níbi kí ẹ máa tí ọrẹ ṣíwájú àwọn ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín ni? Nígbà tí ẹ ò ṣe é, Allāhu sì gba ìronúpìwàdà yín. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[14] Ṣé o ò rí àwọn t’ó mú ìjọ kan tí Allāhu bínú sí ní ọ̀rẹ́? Wọn kì í ṣe ara yín, wọn kò sì jẹ́ ara wọn. Wọ́n yó sì máa búra lórí irọ́, wọ́n sì mọ̀

[15] Allāhu ti pèsè ìyà líle dè wọ́n. Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú

[16] Wọ́n fi ìbúra wọn ṣe ààbò; wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Nítorí náà, ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún wọn

[17] Àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀

[18] Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde pátápátá, wọn yó sì máa búra fún Un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń búra fun yín. Wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ti rí n̄ǹkan ṣe. Gbọ́! Dájúdájú àwọn, àwọn ni òpùrọ́

[19] Èṣù jẹ gàba lé wọn lórí. Ó sì mú wọn gbàgbé ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Èṣù. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ èṣù, àwọn ni ẹni òfò

[20] Dájúdájú àwọn t’ó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn olùyẹpẹrẹ jùlọ

[21] Allāhu kọ ọ́ pé: "Dájúdájú Mo máa borí; Èmi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi." Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí

[22] O ò níí rí ìjọ kan t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn t’ó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kódà kí wọ́n jẹ́ àwọn bàbá wọn, tàbí àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ìbátan wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ti kọ ìgbàgbọ́ òdodo sínú ọkàn wọn. Allāhu sì kún wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ (al-Ƙur’ān àti ìṣẹ́gun) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó sì máa mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Allāhu. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùjèrè

Ìlé-kúrò

Surah 59

[1] Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[2] Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlu-l-kitāb jáde kúrò nínú ilé wọn fún ìkójọ àkọ́kọ́. Ẹ̀yin kò lérò pé wọn yóò jáde. Àwọn náà sì lérò pé dájúdájú àwọn odi ilé wọn yóò dáàbò bo àwọn lọ́dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n Allāhu wá bá wọn ní ibi tí wọn kò lérò; Allāhu sì ju ìbẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn àti ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo wó àwọn ilé wọn. Nítorí náà, ẹ wòye, ẹ̀yin tí ẹ ní ojú ìríran

[3] Àti pé tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ti kọ ìjáde kúrò nínú ìlú Mọdīnah lé àwọn ahlu-l-kitāb lórí ni, dájúdájú (Allāhu) ìbá jẹ wọ́n níyà nílé ayé. Ìyà Iná sì tún wà fún wọn ní ọ̀run

[4] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n yapa (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa (àṣẹ) Allāhu, dájúdájú Allāhu le níbi ìyà

[5] Ẹ̀yin kò níí ge igi dàbínù kan tàbí kí ẹ fi sílẹ̀ kí ó dúró sórí gbòǹgbò rẹ̀, (àfi) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè dójú ti àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ni

[6] Ohunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ wọn fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ẹ ò gbé ẹṣin àti ràkúnmí sáré fún (ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni). Ṣùgbọ́n Allāhu yóò máa fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní agbára lórí ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[7] Ohunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (ó jẹ́) ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ àti ti àwọn ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn tálíkà àti onírìn-àjò tí agara dá nítorí kí ó má baá jẹ́ àdápín láààrin àwọn ọlọ́rọ̀ nínú yín. Ohunkóhun tí Òjíṣẹ́ bá fun yín, ẹ gbà á. Ohunkóhun tí ó bá sì kọ̀ fun yín, ẹ jáwọ́ nínú rẹ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le níbi ìyà

[8] (Ìkógun náà tún wà fún) àwọn aláìní, (ìyẹn,) al-Muhājirūn, àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ilé wọn àti níbi dúkìá wọn, tí wọ́n sì ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí wọ́n sì ń ṣàrànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olódodo

[9] Àwọn t’ó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ òdodo ṣíwájú wọn, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn t’ó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn (ní ìlú Mọdīnah). Wọn kò sì ní bùkátà kan nínú igbá-àyà wọn sí n̄ǹkan tí wọ́n fún wọn. Wọ́n sì ń gbé àjùlọ fún wọn lórí ẹ̀mí ara wọn, kódà kí ó jẹ́ pé àwọn gan-an ní bùkátà (sí ohun tí wọ́n fún wọn). Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè

[10] Àwọn t’ó dé lẹ́yìn wọn ń sọ pé: "Olúwa wa, foríjin àwa àti àwọn ọmọ ìyá wa t’ó ṣíwájú wa nínú ìgbàgbọ́ òdodo. Má ṣe jẹ́ kí inúnibíni wà nínú ọkàn wa sí àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[11] Ṣé o ò rí àwọn t’ó ṣọ̀bẹ-ṣèlu tí wọ́n ń wí fún àwọn ọmọ ìyá wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb, pé "Dájúdájú tí wọ́n bá le yín jáde (kúrò nínú ìlú), àwa náà gbọ́dọ̀ jáde pẹ̀lú yín ni. Àwa kò sì níí tẹ̀lé àṣẹ ẹnì kan lórí yín láéláé. Tí wọ́n bá sì gbé ogun dìde si yín, àwa gbọ́dọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fun yín ni." Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n

[12] Dájúdájú tí wọ́n bá lé wọn jáde, wọn kò níí jáde pẹ̀lú wọn. Dájúdájú tí wọ́n bá sì gbógun tì wọ́n, wọn kò níí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn. Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ wọn, dájúdájú wọn yóò pẹ̀yìn dà (láti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́

[13] Dájúdájú ẹ̀yin ni ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ t’ó lágbára ju Allāhu lọ nínú igbá-àyà wọn. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé

[14] Wọn kò lè parapọ̀ dojú ìjà kọ yín àfi (kí wọ́n) wà nínú odi ìlú tàbí (kí wọ́n wà) lẹ́yìn àwọn ògiri. Ogun ààrin ara wọn gan-an le. Ò ń lérò pé wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ ni, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni ọkàn wọn wà. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ní làákàyè

[15] Àpẹẹrẹ wọn dà bí àwọn t’ó ṣíwájú wọn tí kò tí ì pẹ́ lọ títí. Wọ́n tọ́ aburú ọ̀rọ̀ ara wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[16] Àpẹẹrẹ wọn dà bí Èṣù nígbà tí ó bá wí fún ènìyàn pé: "Ṣàì gbàgbọ́." Nígbà tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ (tán), ó máa wí pé: "Dájúdájú èmi yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Dájúdájú èmi ń páyà Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[17] Nítorí náà, ìkángun àwọn méjèèjì ni pé, dájúdájú àwọn méjèèjì yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni àwọn méjèèjì nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí

[18] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ̀mí kan sì wòye sí ohun tí ó tì ṣíwájú fún ọ̀la (àlùkìyáámọ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[19] Kí ẹ sì má ṣe dà bí àwọn t’ó gbàgbé Allāhu. (Allāhu) sì mú wọn gbàgbé ẹ̀mí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́

[20] Àwọn èrò inú Iná àti àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra kò dọ́gba. Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, àwọn ni olùjèrè

[21] Tí ó bá jẹ́ pé A sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ sórí àpáta ni, dájúdájú o máa rí i tí ó máa wálẹ̀, tí ó máa fọ́ pẹ́tẹpẹ̀tẹ fún ìpáyà Allāhu. Ìwọ̀nyí ni àwọn àpẹẹrẹ tí À ń fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀

[22] Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Òun ni Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[23] Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ọba (ẹ̀dá), Ẹni-mímọ́ jùlọ, Aláìlábùkù, Olùjẹ́rìí-Òjíṣẹ́-Rẹ̀, Olùjẹ́rìí-ẹ̀dá Alágbára, Olùjẹni-nípá, Atóbi. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I

[24] Òun ni Allāhu, Ẹlẹ́dàá, Olùpilẹ̀-ẹ̀dá, Olùyàwòrán-ẹ̀dá. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ t’ó dára jùlọ. Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

Obìnrin tí a gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò

Surah 60

[1] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀tá Mi àti ọ̀tá yín ní ọ̀rẹ́ tí ẹ óò máa fi ìfẹ́ hàn sí. Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ó dé ba yín nínú òdodo. Wọ́n yọ Òjíṣẹ́ àti ẹ̀yin náà kúrò nínú ìlú nítorí pé, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu, Olúwa yín. Tí ẹ̀yin bá jáde fún ogun nítorí ẹ̀sìn Mi àti nítorí wíwá ìyọ́nú Mi, (ṣé) ẹ̀yin yóò tún máa ní ìfẹ́ kọ̀rọ̀ sí wọn ni! Èmi sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ fi pamọ́ àti ohun tí ẹ fi hàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yín, dájúdájú ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà

[2] Tí ọwọ́ wọn bá bà yín, wọ́n máa di ọ̀tá fun yín. Wọn yó sì fi ọwọ́ wọn àti ahọ́n wọn nawọ́ aburú si yín. Wọ́n sì máa fẹ́ kí ó jẹ́ pé ẹ di aláìgbàgbọ́

[3] Àwọn ẹbí yín àti àwọn ọmọ yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní; ní Ọjọ́ Àjíǹde ni Allāhu máa ṣèpínyà láààrin yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[4] Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fun yín ní ara (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. - Àfi ọ̀rọ̀ tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ pé: "Dájúdájú mo máa tọrọ àforíjìn fún ọ, èmi kò sì ní ìkápá kiní kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu. - Olúwa wa, Ìwọ l’a gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ l’a ṣẹ́rí padà sí (nípa ìronúpìwàdà). Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[5] Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Foríjìn wá, Olúwa wa. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[6] Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fun yín ní ara wọn fún ẹni t’ó ń retí (ẹ̀sán) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìn dà, dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn

[7] Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò fi ìfẹ́ sí ààrin ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ mú ní ọ̀tá nínú wọn (ìyẹn, nígbà tí wọ́n bá di mùsùlùmí). Allāhu ni Alágbára. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[8] Allāhu kò kọ̀ fun yín nípa àwọn tí kò gbé ogun tì yín nípa ẹ̀sìn, tí wọn kò sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, pé kí ẹ ṣe dáadáa sí wọn, kí ẹ sì ṣe déédé sí wọn. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-déédé

[9] Ohun tí Allāhu kọ̀ fun yín nípa àwọn t’ó gbógun tì yín nínú ẹ̀sìn, tí wọ́n sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, tí wọ́n tún ṣe ìrànlọ́wọ́ (fún àwọn ọ̀tá yín) láti le yín jáde, ni pé (Ó kọ̀ fun yín) láti mú wọn ní ọ̀rẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí

[10] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá ba yín, tí wọ́n gbé ìlú àwọn aláìgbàgbọ́ jù sílẹ̀ fún ààbò ẹ̀sìn wọn, ẹ bi wọ́n ní ìbéèrè. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, tí ẹ bá mọ̀ wọ́n sí onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin kò lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Ẹ fún (àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin) ní owó tí wọ́n ná (ní owó-orí obìnrin náà). Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà pé kí ẹ fẹ́ wọn nígbà tí ẹ bá ti fún (àwọn obìnrin wọ̀nyí) ní owó-orí wọn. Ẹ má ṣe fi owó-orí àwọn obìnrin yín tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ mú wọn mọ́lẹ̀ (gẹ́gẹ́ bí ìyàwó yín láì jẹ́ pé wọ́n gba ’Islām pẹ̀lú yín). Ẹ bèèrè ohun tí ẹ ná (ní owó-orí wọn lọ́wọ́ aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin tí wọ́n sá lọ bá). Kí àwọn (aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin náà) bèèrè ohun tí àwọn náà ná (ní owó-orí wọn lọ́wọ́ ẹ̀yin tí onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin sá wá bá). Ìyẹn ni ìdájọ́ Allāhu. Ó sì ń dájọ́ láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[11] Tí kiní kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó yín bá bọ́ mọ yín lọ́wọ́ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, tí ẹ sì kórè ogun, ẹ fún àwọn tí ìyàwó wọn sá lọ ní irú òdiwọ̀n ohun tí wọ́n ná (ní owó-orí). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Rẹ̀

[12] Ìwọ Ànábì, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá bá ọ, tí wọ́n ń ṣe àdéhùn fún ọ pé àwọn kò níí fi kiní kan ṣẹbọ sí Allāhu, àwọn kò níí jalè, àwọn kò níí ṣe sìná, àwọn kò níí pa ọmọ wọn, àwọn kò níí mú àdápa irọ́ wá, àdápa irọ́ tí wọ́n ń mú wá láààrin ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn (ìyẹn ni gbígbé oyún olóyún fún ọkọ wọn), àwọn kò sì níí yapa rẹ níbi n̄ǹkan dáadáa, nígbà náà bá wọn ṣe àdéhùn, kí ó sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[13] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ìjọ kan tí Allāhu ti bínú sí ní ọ̀rẹ́. Dájúdájú wọ́n ti sọ̀rètí nù nípa ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ t’ó wà nínú sàréè (ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́)

Àwọn Safu

Surah 61

[1] Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[2] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí kí ni ẹ ṣe ń sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe níṣẹ́

[3] Ó jẹ́ ohun ìbínú t’ó tóbi ní ọ̀dọ̀ Allāhu pé kí ẹ sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe

[4] Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn t’ó ń jagun fún ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí wọ́n tò ní) ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí ẹni pé ogiri ilé tí wọ́n lẹ̀ pọ̀ mọ́ra wọn ni wọ́n

[5] (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ óò ṣe fi ìnira kàn mí. Ẹ sì kúkú mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ni èmi jẹ́ si yín." Nígbà tí wọ́n sì yẹ̀ (kúrò níbi òdodo), Allāhu yẹ ọkàn wọn. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[6] (Rántí) nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu si yín. Mò ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú mi nínú Taorāh. Mo sì ń mú ìró-ìdùnnú wá nípa Òjíṣẹ́ kan t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Orúkọ rẹ̀ ni ’Ahmọd." Nígbà tí ó bá sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, wọ́n á wí pé: "Idán pọ́nńbélé ni èyí

[7] Ta sì ni ó ṣàbòsí t’ó tayọ ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tí wọ́n sì ń pè é sínú ’Islām! Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[8] Wọ́n ń gbèrò láti fi (ọ̀rọ̀) ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ Allāhu. Allāhu yó sì mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn kárí, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀

[9] (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀

[10] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ṣé kí N̄g tọ́ka yín sí òkòwò kan tí ó máa gbà yín là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[11] Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ẹ jagun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀

[12] (Allāhu) máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ibùgbé t’ó dára nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá

[13] Àti n̄ǹkan mìíràn tí ẹ tún nífẹ̀ẹ́ sí; (ìyẹn,) àrànṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti ìṣẹ́gun t’ó súnmọ́. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú

[14] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ alárànṣe fún ẹ̀sìn Allāhu gẹ́gẹ́ bí (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ṣe sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: "Ta ni ó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi nípa ẹ̀sìn Allāhu?" Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ pé: "Àwa ni alárànṣe fún ẹ̀sìn Allāhu." Igun kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbà á gbọ́ ní òdodo nígbà náà, igun kan sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. A sì fún àwọn t’ó gbàgbọ́ lágbára lórí àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì di olùborí

Ọjọ́ Ìsinmi

Surah 62

[1] Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu, Ọba ẹ̀dá, Ẹni-Mímọ́ jùlọ, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[2] Òun ni Ẹni tí Ó gbé dìde láààrin àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) Òjíṣẹ́ kan lára wọn. Ó ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[3] (Iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ tún wà fún) àwọn mìíràn tí wọ́n máa wà nínú àwọn (ọmọlẹ́yìn rẹ̀), àmọ́ tí wọn kò tí ì rìn kàn wọ́n. (Allāhu) Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

[4] Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore-àjùlọ ńlá

[5] Àpèjúwe ìjọ tí A fún ní Taorāh, lẹ́yìn náà tí wọn kò tẹ̀lé e, ó dà bí àpèjúwe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ru ẹrù àwọn tírà. Aburú ni àpèjúwe àwọn t’ó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí

[6] Sọ pé: "Ẹ̀yin yẹhudi, tí ẹ bá lérò pé dájúdájú ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ Allāhu dípò àwọn ènìyàn (yòókù), ẹ tọrọ ikú nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[7] Wọn kò níí tọrọ rẹ̀ láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn ti tì ṣíwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí

[8] Sọ pé: "Dájúdájú ikú tí ẹ̀ ń sá fún, dájúdájú ó máa pàdé yín. Lẹ́yìn náà, wọn yóò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[9] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá pe ìrun ní ọjọ́ Jum‘ah, ẹ yára lọ síbi ìrántí Allāhu, kí ẹ sì pa kátà-kárà tì. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀

[10] Nígbà tí wọ́n bá sì parí ìrun, ẹ túká sí orí ilẹ̀, kí ẹ sì máa wa nínú oore Allāhu. Ẹ rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè

[11] Nígbà tí wọ́n bá rí ọjà kan tàbí ìranù kan, wọn yóò dà lọ síbẹ̀. Wọn yó sì fi ọ́ sílẹ̀ lórí ìdúró. Sọ pé: "N̄ǹkan tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu l’óore ju ìranù àti ọjà lọ. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè

Àwọn Alágàbàgebè

Surah 63

[1] Nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí bá wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n á wí pé: “À ń jẹ́rìí pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Allāhu ni ọ́.” Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ọ́. Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, òpùrọ́ ni wọ́n

[2] Wọ́n fi àwọn ìbúra wọn ṣe ààbò (fún ẹ̀mí ara wọn), wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú

[3] (Wọ́n ṣe) ìyẹn nítorí pé wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, A ti fi èdídí dí ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́ àgbọ́yé

[4] Nígbà tí o bá rí wọn, ìrísí wọn yóò jọ ọ́ lójú. Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ìwọ yóò tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sì dà bí igi tí wọ́n gbé ti ògiri. Wọ́n sì ń lérò pé gbogbo igbe (ìbòsí) ń bẹ lórí wọn (nípa ìṣọ̀bẹ-ṣèlu wọn). Ọ̀tá ni wọ́n. Nítorí náà, ṣọ́ra fún wọn. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo

[5] Àti pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá kí Òjíṣẹ́ ba yín tọrọ àforíjìn.” Wọ́n á gbúnrí. O sì máa rí wọn tí wọn yóò máa gbúnrí lọ, tí wọn yóò máa ṣègbéraga

[6] Bákan náà ni fún wọn; yálà o bá wọn tọrọ àforíjìn tàbí o ò bá wọn tọrọ àforíjìn. Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu kò nií fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́

[7] Àwọn ni àwọn t’ó ń wí pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ná owó fún àwọn t’ó wà lọ́dọ̀ Ójíṣẹ́ Allāhu títí wọn yóò fi fọ́nká. Ti Allāhu sì ni àwọn àpótí-ọrọ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò níí gbọ́ àgbọ́yé

[8] Wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú tí a bá padà dé sínú ìlú Mọdīnah, ńṣe ni àwọn alágbára (ìlú) yóò yọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ jáde kúrò nínú ìlú." Agbára sì ń jẹ́ ti Allāhu, àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò mọ̀

[9] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín kó àìrójú ba yín níbi ìrántí Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kó sínú (àìrójú) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò

[10] Ẹ ná nínú ohun tí A pèsè fun yín ṣíwájú kí ikú tó dé bá ẹnì kan yín, kí ó wá wí pé: "Olúwa mi, kí ó sì jẹ́ pé O lọ́ mi lára sí i títí di ìgbà kan tó súnmọ́, èmi ìbá sì lè máa tọrẹ, èmi ìbá sì wà lára àwọn ẹni rere

[11] Allāhu kò sì níí lọ́ ẹ̀mí kan lára nígbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ bá dé. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

Ìjákulẹ̀

Surah 64

[1] Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu. TiRẹ̀ ni ìjọba. TiRẹ̀ sì ni ọpẹ́. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[2] Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Aláìgbàgbọ́ wà nínú yín. Onígbàgbọ́ òdodo sì wà nínú yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe

[3] Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ya àwòrán yín. Ó sì ṣe àwọn àwòrán yín dáradára. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá

[4] Ó mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá

[5] Ṣé ìró àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìṣáájú kò tí ì dé ba yín ni? Nítorí náà, wọ́n tọ́ ìyà ọ̀ràn wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn

[6] Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. Wọ́n sì wí pé: "Ṣé abara l’ó máa fi ọ̀nà mọ̀ wá?" Nítorí náà, wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Wọ́n sì pẹ̀yìn dà (sí òdodo). Allāhu sì rọrọ̀ láì sí àwọn. Àti pé Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́

[7] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé A ò níí gbé wọn dìde. Sọ pé: "Bẹ́ẹ̀ kọ́, mo fi Olúwa mi búra, dájúdájú Wọn yóò gbe yín dìde. Lẹ́yìn náà, Wọn yóò fun yín ní ìró ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu

[8] Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ tí A sọ̀kalẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe

[9] Ní ọjọ́ tí (Allāhu) yóò ko yín jọ fún ọjọ́ àkójọ. Ìyẹn ni ọjọ́ èrè àti àdánù. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ fún un. Ó sì máa mú un wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá

[10] Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú

[11] Àdánwò kan kò lè ṣẹlẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́, Allāhu máa fi ọkàn rẹ̀ mọ̀nà. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan

[12] Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá gbúnrí, iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé lojúṣe Òjíṣẹ́ Wa

[13] Allāhu, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé

[14] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọ̀tá wà fun yín nínú àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún wọn. Tí ẹ bá ṣàmójúkúrò, tí ẹ ṣàfojúfò, tí ẹ sì ṣàforíjìn (fún wọn), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[15] Ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín. Allāhu sì ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀

[16] Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ (Allāhu), ẹ tẹ̀lé e, kí ẹ sì náwó (fún ẹ̀sìn Rẹ̀) lóore jùlọ fún ẹ̀mí yín. Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè

[17] Tí ẹ bá yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára, Ó máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fun yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Olùmoore, Aláfaradà

[18] Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n

Ìkọ̀sílẹ̀

Surah 65

[1] Ìwọ Ànábì, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe òǹkà ọjọ́ opó fún ìkọ̀sílẹ̀ wọn. Kí ẹ sì ṣọ́ òǹkà ọjọ́ opó. Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu, Olúwa yín. Ẹ má ṣe mú wọn jáde kúrò nínú ilé wọn, àwọn náà kò sì gbọdọ̀ jáde àfi tí wọ́n bá lọ ṣe ìbàjẹ́ t’ó fojú hàn. Ìwọ̀nyẹn sì ni àwọn ẹnu-àlà tí Allāhu gbékalẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-àlà tí Allāhu gbékalẹ̀, o kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ kò sì mọ̀ bóyá Allāhu máa mú ọ̀rọ̀ titun ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn

[2] Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ parí òǹkà ọjọ́ opó wọn, ẹ mú wọn mọ́dọ̀ ní ọ̀nà t’ó dára tàbí kí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára. Ẹ fi àwọn onídéédé méjì nínú yín jẹ́rìí sí i. Kí ẹ sì gbé ìjẹ́rìí náà dúró ní tìtorí ti Allāhu. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fún un ní ọ̀nà àbáyọ (nínú ìṣòro)

[3] Ó sì máa pèsè fún un ní àyè tí kò ti rokàn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Allāhu, Ó máa tó o. Dájúdájú Allāhu yóò mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ dé òpin. Dájúdájú Allāhu ti kọ òdíwọ̀n àkókò fún gbogbo n̄ǹkan

[4] Àwọn obìnrin t’ó ti sọ̀rètí nù nípa n̄ǹkan oṣù ṣíṣe nínú àwọn obìnrin yín, tí ẹ bá ṣeyèméjì, òǹkà ọjọ́ ìkọ̀sílẹ̀ wọn ni oṣù mẹ́ta. (Bẹ́ẹ̀ náà ni fún) àwọn tí kò tí ì máa ṣe n̄ǹkan oṣù. Àwọn olóyún, ìparí òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tiwọn ni pé kí wọ́n bí oyún inú wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa ṣe ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn

[5] Ìyẹn ni àṣẹ Allāhu, tí Ó sọ̀kalẹ̀ fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́. Ó sì máa jẹ́ kí ẹ̀san rẹ̀ tóbi

[6] Ẹ fún wọn ní ibùgbé nínú ibùgbé yín bí àyè ṣe gbà yín mọ. Ẹ má ṣe ni wọ́n lára láti kó ìfúnpinpin bá wọn. Tí wọ́n bá jẹ́ olóyún, ẹ náwó lé wọn lórí títí wọn yóò fi bí oyún inú wọn. Tí wọ́n bá ń fún ọmọ yín ní ọyàn mu, ẹ fún wọn ní owó-ọ̀yà wọn. Ẹ dámọ̀ràn láààrin ara yín ní ọ̀nà t’ó dára. Tí ọ̀rọ̀ kò bá sì rọgbọ láààrin ara yín, kí ẹlòmíìràn bá ọkọ (fún ọmọ) ní ọyàn mu

[7] Kí ọlọ́rọ̀ ná nínú ọrọ̀ rẹ̀. Ẹni tí A sì díwọ̀n arísìkí rẹ̀ fún (níwọ̀nba), kí ó ná nínú ohun tí Allāhu fún un. Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi n̄ǹkan tí Ó fún un. Allāhu yó sì mú ìrọ̀rùn wá lẹ́yìn ìnira

[8] Mélòó mélòó nínú àwọn ìlú tí wọ́n yapa àṣẹ Olúwa Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A sì máa ṣírò iṣẹ́ wọn ní ìṣírò líle. Àti pé A máa jẹ wọ́n níyà t’ó burú gan-an

[9] Nítorí náà, wọn tọ́ ìyà ọ̀ràn wọn wò. Ìkángun ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ́ òfò

[10] Allāhu ti pèsè ìyà líle sílẹ̀ dè wọ́n. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, ẹ̀yin onílàákàyè tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo. Allāhu kúkú ti sọ ìrántí kalẹ̀ fun yín

[11] Òjíṣẹ́ kan tí ó máa ké àwọn āyah Allāhu t’ó yanjú fun yín nítorí kí ó lè mú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kúrò nínú àwọn òkùnkùn lọ sínú ìmọ́lẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́ ní òdodo, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ rere, Ó máa mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Dájúdájú Allāhu ti ṣe arísìkí t’ó dára jùlọ fún un

[12] Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ méje àti ilẹ̀ ní (òǹkà) irú rẹ̀. Àṣẹ ń sọ̀kalẹ̀ láààrin wọn nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àti pé dájúdájú Allāhu fi ìmọ̀ rọ̀gbà yí gbogbo n̄ǹkan ká

Ìfòfindè

Surah 66

[1] Ìwọ Ànábì, nítorí kí ni o ṣe máa sọ n̄ǹkan tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ di èèwọ̀? Ìwọ ń wá ìyọ́nú àwọn ìyàwó rẹ. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

[2] Dájúdájú Allāhu ti ṣe àlàyé òfin ìtánràn ìbúra yín fun yín. Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ yín. Òun sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[3] Rántí nígbà tí Ànábì bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ s’ọ̀rọ̀ àṣírí. Nígbà tí (ẹni t’ó bá sọ̀rọ̀, ìyẹn Hafsọh) sì sọ̀rọ̀ náà fún (‘Ā’iṣah), Allāhu sì fi han Ànábì (pé ẹlòmíìràn ti gbọ́ sí i). Ànábì sì sọ apá kan rẹ̀ (fún Hafsọh pé: "O ti fi ọ̀rọ̀ Mọ̄riyah tó ‘Ā’iṣah létí."). Ó sì fi apá kan sílẹ̀ (ìyẹn, ọ̀rọ̀ nípa ipò àrólé). Àmọ́ nígbà tí (Ànábì) fi ìró náà tó o létí, Hafsọh) sọ pé: "Ta ni ó fún ọ ní ìró èyí?" (Ànábì) sọ pé: "Onímọ̀, Alámọ̀tán l’Ó fún mi ní ìró náà

[4] Tí ẹ̀yin méjèèjì bá ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu, (Ó máa gba ìronúpìwàdà yín). Ṣebí ọkàn yín kúkú ti tẹ̀ (síbi kí Ànábì má fẹ̀ẹ́ Mọ̄riyah). Tí ẹ bá sì ran ara yín lọ́wọ́ (láti kó ìbànújẹ́) bá a, dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, àti (mọlāika) Jibrīl àti ẹni rere nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn mọlāika tí wọ́n jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (tún wà fún un)

[5] Ó ṣeé ṣe, tí ó bá kọ̀ yín sílẹ̀, kí Olúwa rẹ̀ fi àwọn obìnrin kan, tí wọn lóore jù yín lọ rọ́pò fún un, (tí wọ́n máa jẹ́) mùsùlùmí, onígbàgbọ́ òdodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ, àwọn olùronúpìwàdà, olùjọ́sìn, olùgbààwẹ̀ ní adélébọ̀ àti wúńdíá

[6] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí ara yín àti àwọn ará ilé yín níbi Iná. Ènìyàn àti òkúta ni n̄ǹkan ìkoná rẹ̀. Àwọn mọlāika t’ó rorò, tí wọ́n le ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. Wọn kò níí yapa àṣẹ Allāhu níbi ohun tí Ó bá pa láṣẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá pa láṣẹ fún wọn

[7] Ẹ̀yin tí ẹ ṣàì gbàgbọ́, ẹ má ṣe ṣàròyé ní ọjọ́ òní. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san

[8] Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní ìronúpìwàdà òdodo. Ó ṣeé ṣe pé Olúwa yín máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fun yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ tí Allāhu kò níí dójú ti Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọn yóò sọ pé: "Olúwa wa, pé ìmọ́lẹ̀ wa fún wa, kí O sì foríjìn wá. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[9] Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Ibùgbé wọn sì ni iná Jahanamọ. Ìkángun náà sì burú

[10] Allāhu fi ìyàwó (Ànábì) Nūh àti ìyàwó (Ànábì) Lūt ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Àwọn méjèèjì wà lábẹ́ ẹrúsìn méjì rere nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Àwọn (obìnrin) méjèèjì sì jàǹbá àwọn ọkọ wọn. Àwọn ọkọ wọn kò sì fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. A ó sì sọ fún àwọn obìnrin méjèèjì pé: "Ẹ wọ inú Iná pẹ̀lú àwọn olùwọlé (sínú Iná)

[11] Allāhu tún fi ìyàwó Fir‘aon ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn t’ó gbàgbọ́. Nígbà tí ó sọ pé: "Olúwa mi, kọ́ ilé kan fún mi lọ́dọ̀ Rẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Là mí lọ́wọ́ Fir‘aon àti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Kí O sì là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí

[12] Àti Mọryam ọmọbìnrin ‘Imrọ̄n, èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn sí i lára nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá. Ó gbàgbọ́ lódodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ̀ àti àwọn Tírà Rẹ̀. Ó sì wà nínú àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu

Àkóso

Surah 67

[1] Ìbùkún ni fún Ẹni tí ìjọba wà ní Ọwọ́ Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan

[2] Ẹni tí Ó dá ikú àti ìṣẹ̀mí nítorí kí ó lè dan yín wò; èwo nínú yín l’ó máa ṣe iṣẹ́ rere jùlọ. Òun sì ni Alágbára, Aláforíjìn

[3] Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele. O ò lè rí àìgúnrégé kan lára ẹ̀dá Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, wò ó padà, ǹjẹ́ o rí ojú sísán kan (lára sánmọ̀)

[4] Lẹ́yìn náà, wò ó padà ní ẹ̀ẹ̀ mejì, kí ojú rẹ padà sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ. Ó sì máa káàárẹ̀

[5] Dájúdájú A ti fi (àwọn ìràwọ̀ t’ó ń tànmọ́lẹ̀ bí) àtùpà ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́. A tún ṣe wọ́n ni ẹ̀ta-ìràwọ̀ tí wọ́n ń jù mọ́ àwọn èṣù. A sì pèsè ìyà Iná t’ó ń jò fòfò sílẹ̀ dè wọ́n

[6] Ìyà iná Jahanamọ sì wà fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Ìkángun náà sì burú

[7] Nígbà tí wọ́n bá jù wọ́n sínú rẹ̀, wọn yóò máa gbọ́ kíkùn rẹ̀, tí ó sì máa ru sókè

[8] Iná máa fẹ́ẹ̀ pínra rẹ̀ láti ara ìbínú. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ju ìjọ kan sínú rẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ Iná yóò máa bi wọ́n léèrè pé: "Ǹjẹ́ olùkìlọ̀ kan kò wá ba yín bí

[9] Wọn yóò wí pé: "Rárá, dájúdájú olùkìlọ̀ kan ti wá bá wa, ṣùgbọ́n a pè é ní òpùrọ́. A sì wí pé Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé ẹ wà nínú ìṣìnà t’ó tóbi

[10] Wọ́n tún wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé a gbọ́ràn ni tàbí pé a ṣe làákàyè ni, àwa kò níí wà nínú èrò inú Iná jíjò

[11] Wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu yó wà fún àwọn èrò inú Iná t’ó ń jò fòfò

[12] Dájúdájú àwọn t’ó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi ń bẹ fún wọn

[13] Ẹ wí ọ̀rọ̀ yín ní jẹ́ẹ́jẹ́ tàbí ẹ wí i sókè, dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun t’ó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá

[14] Ṣé (Allāhu) kò mọ ẹni t’Ó dá ni? Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán

[15] Òun ni Ẹni tí Ó rọ ilẹ̀ fun yín. Nítorí náà, ẹ rìn ní àwọn agbègbè rẹ̀ káàkiri, kí ẹ sì jẹ nínú arísìkí Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àjíǹde ẹ̀dá wà

[16] Ṣé ẹ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè jẹ́ kí ilẹ̀ gbe yín mì? Nígbà náà, ilẹ̀ yó sì máa mì tìtì

[17] Tàbí ẹ̀ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín ni? Nígbà náà, ẹ sì máa mọ bí ìkìlọ̀ Mi ti rí

[18] Àwọn t’ó ṣíwájú wọn kúkú pe òdodo nírọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí

[19] Ṣé wọn kò rí àwọn ẹyẹ tí ó wà ní òkè wọn, tí (wọ́n) ń na ìyẹ́ apá (wọn), tí wọ́n sì ń pa á mọ́ra? Kiní kan kò mú wọn dúró (sínú òfurufú) àfi Àjọkẹ́-ayé. Dájúdájú Òun sì ni Olùríran nípa gbogbo n̄ǹkan

[20] Ta ni ẹni tí ó máa jẹ́ ọmọ ogun fun yín, tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé? (Nínú) kí ni àwọn aláìgbàgbọ́ wà bí kò ṣe nínú ẹ̀tàn

[21] Ta ni ẹni tí ó máa pèsè fun yín tí Ó bá dá arísìkí Rẹ̀ dúró? Ńṣe ni wọ́n ń ṣorí kunkun sí i nínú ìgbéraga àti sísá fún òdodo

[22] Ǹjẹ́ ẹni t’ó ń rìn ní ìdojúbolẹ̀ l’ó mọ̀nà jùlọ ni tàbí ẹni t’ó ń rìn sàn án lójú ọ̀nà tààrà

[23] Sọ pé: "Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti àwọn ọkàn fun yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀

[24] Sọ pé: "Òun ni Ẹni tí Ó da yín sí orí ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò ko yín jọ sí

[25] Wọ́n ń wí pé: "Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo

[26] Sọ pé: "Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni ìmọ̀ (nípa) rẹ̀ wà. Èmi kàn jẹ́ olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni

[27] Nígbà tí wọ́n bá rí i t’ó súnmọ́, ojú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò korò wá fún ìbànújẹ́. A ó sì sọ fún wọn pé: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè

[28] Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá pa èmi àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi rẹ́, tàbí tí Ó bá kẹ́ wa (ṣé ẹ lè dí I lọ́wọ́ ni?) Nítorí náà, ta ni ó máa gba àwọn aláìgbàgbọ́ là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[29] Sọ pé: "Òun ni Àjọkẹ́-ayé. Àwa gbà Á gbọ́. Òun sì la gbáralé. Láìpẹ́ ẹ máa mọ ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé

[30] Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí omi yín bá gbẹ wá, ta ni ẹni tí ó máa mú omi ìṣẹ́lẹ̀rú wá ba yín

Kàlámù

Surah 68

[1] Nūn. (Allāhu búra pẹ̀lú) gègé ìkọ̀wé àti ohun tí àwọn mọlāika ń kọ sílẹ̀

[2] Ìwọ kì í ṣe wèrè nípa ìdẹ̀ra Olúwa rẹ

[3] Àti pé dájúdájú ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró ti wà fún ọ

[4] Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà àpọ́nlé

[5] Láìpẹ́ ìwọ yóò rí i, àwọn náà yó sì rí i

[6] èwo nínú yín ni wèrè

[7] Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà

[8] Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[9] Àti pé wọ́n fẹ́ kí o dẹwọ́, kí àwọn náà sì dẹwọ́

[10] Má ṣe tẹ̀lé gbogbo ẹni tí ìbúra rẹ̀ pọ̀, ẹni yẹpẹrẹ

[11] abúni, alárìnká t’ó ń sòfófó kiri

[12] olùdènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀

[13] ọ̀dájú. Lẹ́yìn ìyẹn, àsáwọ̀ ni

[14] Nítorí pé ó ní dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin

[15] nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)”

[16] A máa fi àmì sí i ní góńgórí imú

[17] Dájúdájú Àwa dán wọn wò gẹ́gẹ́ bí A ṣe dán àwọn ọlọ́gbà wò nígbà tí wọ́n búra pé dájúdájú àwọn yóò ká gbogbo èso ọgbà náà ní òwúrọ̀ kùtùkùtù

[18] Wọn kò sì ṣe àyàfi pé "tí Allāhu bá fẹ́

[19] Àdánwò t’ó ń yí n̄ǹkan po láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì yí ọgbà náà po, nígbà tí wọ́n sùn lọ

[20] Ó sì dà bí oko àgédànù (tí wọ́n ti résun)

[21] Wọ́n ń pera wọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù

[22] pé ẹ jí lọ sí oko yín tí ẹ bá fẹ́ ká èso

[23] Wọ́n lọ, wọ́n sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀

[24] pé ní òní mẹ̀kúnnù kan kò gbọdọ̀ wọnú rẹ̀ wá ba yín

[25] Wọ́n jí lọ lórí èrò-ọkàn kan (pé) àwọn lágbára

[26] Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa ti ṣìnà

[27] Rárá o, wọ́n ṣe ìkórè oko léèwọ̀ fún wa ni

[28] Ẹni t’ó dúró déédé jùlọ nínú wọn sọ pé: "Ṣé èmi kò sọ fun yín pé ẹ̀yin kò ṣe ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu (pé "a máa kórè oko wa, ’in ṣā ’Allāhu)

[29] Wọ́n wí pé: "Mímọ́ ni fún Olúwa wa, dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí

[30] Apá kan wọn kọjú sí apá kan; wọ́n sì ń dára wọn lẹ́bi

[31] Wọ́n wí pé: "Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ olùtayọ-ẹnu àlà

[32] Ó ṣeé ṣe kí Olúwa wa fi èyí t’ó dára ju èyí lọ pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa ń rokàn oore sí

[33] Báyẹn ni ìyà náà ṣe rí (fún wọn). Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀

[34] Dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún àwọn olùbẹ̀rù lọ́dọ̀ Olúwa wọn

[35] Ṣé A máa ṣe àwọn mùsùlùmí bí (A ṣe máa ṣe) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí

[36] Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí ná

[37] Tàbí tírà kan wà fun yín tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀

[38] pé dájúdájú ẹ̀yin lẹ ni ohun tí ẹ bá ń ṣà lẹ́ṣà nínú ìdájọ́

[39] Ǹjẹ́ ẹ ni àwọn àdéhùn kan lọ́dọ̀ wa tí ó máa wà títí di Ọjọ́ Àjíǹde pé: "Dájúdájú tiyín ni ìdájọ́ tí ẹ bá ti mú wá

[40] Bi wọ́n léèrè wò pé èwo nínú wọn l’ó lè fọwọ́ ìyẹn sọ̀yà

[41] Tàbí wọ́n ní àwọn òrìṣà kan? Kí wọ́n mú àwọn òrìṣà wọn wá nígbà náà tí wọ́n bá jẹ́ olódodo

[42] Ní ọjọ́ tí A máa ṣí ojúgun sílẹ̀, A sì máa pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀, wọn kò sì níí lè ṣe é

[43] Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n kúkú ti pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀ nígbà tí wọ́n ní àlàáfíà (wọn kò sì kírun)

[44] Nítorí náà, fi Èmi àti ẹni t’ó ń pe ọ̀rọ̀ yìí nírọ́ sílẹ̀. A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò mọ̀

[45] Mò ń lọ́ra fún wọn ni. Dájúdájú ète Mi lágbára

[46] Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́dọ̀ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn

[47] Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni (wàláà) ìkọ̀kọ̀ wà ni wọ́n bá ń kọ ọ́ (síta)

[48] Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Kí ìwọ má sì ṣe dà bí ẹlẹ́ja (ìyẹn, Ànábì Yūnus) nígbà tí ó pe (Allāhu) pẹ̀lú ìbànújẹ́

[49] Tí kò bá jẹ́ pé ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ lé e bá, wọn ìbá jù ú sórí ilẹ̀ gban̄sasa (láti inú ẹja) ní ẹni-èébú

[50] Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì ṣe é ní ara àwọn ẹni rere

[51] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ẹ̀ fi ojú wọn gbé ọ ṣubú nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrántí náà. Wọ́n sì ń wí pé: "Dájúdájú wèrè mà ni

[52] Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá

Òtítọ́

Surah 69

[1] Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo

[2] Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo

[3] Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo

[4] Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Ìpáyà nírọ́

[5] Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́

[6] Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́

[7] Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù t’ó ti luhò nínú ni wọ́n

[8] Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn t’ó ṣẹ́ kù bí

[9] Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe

[10] Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú àlékún

[11] Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-àlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi

[12] Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fun yín àti nítorí kí etí t’ó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ

[13] Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan

[14] tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan

[15] ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀

[16] Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn

[17] Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ

[18] Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan t’ó máa pamọ́ (fún Wa)

[19] Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: "Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi

[20] Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé

[21] Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó máa yọ́nú sí

[22] nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga

[23] Àwọn èso rẹ̀ (sì) wà ní àrọ́wọ́tó

[24] Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá

[25] Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: "Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi! méjéèjì ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé ọwọ́ òsì ni aláìgbàgbọ́ máa tì bọ inú igbá-àyà rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi gba ìwé iṣẹ́ rẹ̀

[26] Àti pé èmi kò mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́

[27] Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá)

[28] Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀

[29] Agbára mi sì ti parun

[30] Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn

[31] Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀

[32] Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u ni kí ẹ kì í sí

[33] Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi

[34] Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù

[35] Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní

[36] Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọyúnwẹ̀jẹ̀

[37] Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

[38] Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú ohun tí ẹ̀ ń fojú rí

[39] àti ohun tí ẹ ò fojú rí

[40] Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé

[41] Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀

[42] Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí

[43] Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[44] Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni

[45] Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún

[46] Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀

[47] Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa)

[48] Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[49] Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn t’ó ń pe al-Ƙur’ān nírọ́ wà nínú yín

[50] Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́

[51] Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo t’ó dájú

[52] Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi

Àwọn Ọ̀nà Ìgòkè

Surah 70

[1] Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà t’ó máa ṣẹlẹ̀

[2] sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́

[3] lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga

[4] Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín)

[5] Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù t’ó rẹwà

[6] Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun t’ó jìnnà

[7] A sì ń wò ó ní ohun t’ó súnmọ́

[8] (Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí idẹ t’ó yọ́

[9] àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun

[10] ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀)

[11] Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn

[12] Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀

[13] àti àwọn ẹbí rẹ̀ t’ó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé

[14] àti gbogbo ẹni t’ó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná)

[15] Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná t’ó ń jò fòfò)

[16] Ó máa bó awọ orí tòró

[17] (Iná) yó máa ké sí ẹni t’ó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i

[18] ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn)

[19] Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà

[20] Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó

[21] Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì tẹ oore, ó máa yahun

[22] Àyàfi àwọn olùkírun

[23] àwọn olùdúnnímọ́ ìrun wọn

[24] àwọn t’ó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn

[25] sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún

[26] àwọn t’ó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo

[27] àwọn t’ó ń páyà ìyà Olúwa wọn

[28] dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí

[29] àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn

[30] àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú

[31] nítorí náà, ẹni kẹ́ni t’ó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ-ẹnu àlà

[32] àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn

[33] àwọn t’ó ń dúró ti ìjẹ́rìí wọn

[34] àti àwọn t’ó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn

[35] Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

[36] Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ

[37] tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)

[38] Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni

[39] Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀

[40] Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn , dájúdájú Àwa ni Alágbára

[41] láti lè fi àwọn t’ó dára jù wọ́n lọ pààrọ̀ wọn. Kò sì sí ẹni t’ó lè kó agara bá Wa

[42] Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

[43] Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan

[44] Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn

Núhù

Surah 71

[1] Dájúdájú Àwa rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣèkìlọ̀ fún ìjọ rẹ ṣíwájú kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó dé bá wọn

[2] Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín

[3] pé kí ẹ jọ́sìn fún Allāhu, kí ẹ bẹ̀rù Rẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀lé mi

[4] (Allāhu) máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fun yín. Ó sì máa lọ yín lára títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àkókò (ikú tí) Allāhu (kọ mọ́ ẹ̀dá), nígbà tí ó bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀

[5] Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi pe ìjọ mi ní òru àti ní ọ̀sán

[6] Ìpè mi kò sì ṣe àlékún kan fún wọn àyàfi sísá sẹ́yìn (fún òdodo)

[7] Àti pé ìgbàkígbà tí mo bá pè wọ́n pé kí O lè foríjìn wọ́n, wọ́n ń fi ọmọníka wọn dí etí wọn, wọ́n ń yíṣọ wọn borí, wọ́n ń takú (sórí ẹ̀ṣẹ̀), wọ́n sì ń ṣègbéraga gan-an

[8] Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi pè wọ́n pẹ̀lú ohùn òkè

[9] Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi kéde fún wọn, mo sì tún pè wọ́n ní ìdá kọ́ńkọ́

[10] Mo sì sọ pé, ẹ tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín, dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn

[11] Ó máa rọ̀jò fun yín ní òjò púpọ̀

[12] Ó máa fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin ràn yín lọ́wọ́. Ó máa ṣe àwọn ọgbà oko fun yín. Ó sì máa ṣe àwọn odò fun yín

[13] Kí ló mu yín tí ẹ kò páyà títóbi Allāhu

[14] Ó sì kúkú ṣẹ̀dá yín láti ìrísí kan sí òmíràn (nínú oyún)

[15] Ṣé ẹ ò rí bí Allāhu ṣe dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele ni

[16] Ó sì ṣe òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú wọn. Ó tún ṣe òòrùn ní àtùpà

[17] Allāhu mu yín jáde láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀

[18] Lẹ́yìn náà, Ó máa da yín padà sínú rẹ̀. Ó sì máa mu yín jáde tààrà

[19] Allāhu ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́

[20] nítorí kí ẹ lè tọ àwọn ojú ọ̀nà fífẹ̀ gbẹ̀gẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀

[21] (Ànábì) Nūh sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú wọ́n yapa mi. Wọ́n sì tẹ̀lé ẹni tí dúkìá rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún bí kò ṣe òfò

[22] Wọ́n sì déte ní ète t’ó tóbi

[23] Wọ́n sì wí pé: "Ẹ má ṣe fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀. Ẹ má ṣe fi òrìṣà Wadd, Suwā‘u, Yẹgūth, Yẹ‘ūƙ àti Nasr sílẹ̀

[24] Dájúdájú wọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ṣìnà. (Olúwa mi) má ṣe jẹ́ kí àwọn alábòsí lékún ní kiní kan bí kò ṣe ìṣìnà

[25] Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Wọ́n sì máa fi wọ́n sínú Iná. Wọn kò sì níí rí àwọn alárànṣe fún wọn lẹ́yìn Allāhu

[26] (Ànábì) Nūh tún sọ pé: "Olúwa mi, má ṣe fi ẹnì kan kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ lórí ilẹ̀

[27] Dájúdájú tí Ìwọ bá fi wọ́n sílẹ̀, wọn yóò kó ìṣìnà bá àwọn ẹrú Rẹ. Wọn kò sì níí bí ọmọ kan àfi ẹni burúkú, aláìgbàgbọ́

[28] Olúwa mi foríjìn èmi, àwọn òbí mi méjèèjì àti ẹni t’ó bá wọ inú ilé mi (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Má sì ṣàlékún kan fún àwọn alábòsí àfi ìparun

Àwọn Jinnì

Surah 72

[1] Sọ pé: "Wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé dájúdájú ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú tẹ́tí (sí al-Ƙur’ān)." Wọ́n sì sọ pé: "Dájúdájú àwa gbọ́ al-Ƙur’ān ìyanu

[2] Ó ń ṣètọ́sọ́nà síbi ìmọ̀nà. Nítorí náà, a gbà á gbọ́. Àwa kò sì níí fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa wa

[3] Àti pé dájúdájú títóbi Olúwa wa ga. Kò fi ẹnì kan kan ṣe aya àti ọmọ

[4] Dájúdájú òmùgọ̀ nínú wa máa ń sọ ìsọkúsọ nípa Allāhu

[5] Dájúdájú àwa sì ń rò pé ènìyàn àti àlùjànnú kò níí pa irọ́ mọ́ Allāhu ni

[6] Àti pé dájúdájú àwọn ọkùnrin kan nínú ènìyàn máa ń fi àwọn ọkùnrin kan nínú àwọn àlùjànnú wá ààbò. Àwọn àlùjànnú sì ṣe àlékún aburú fún wọn

[7] Dájúdájú àwọn àlùjànnú lérò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ènìyàn náà ṣe lérò pé Allāhu kò níí gbé ẹnì kan kan dìde (lẹ́yìn ikú)

[8] Dájúdájú àwa wá (ọ̀rọ̀ àyọ́gbọ́) wá sí sánmọ̀, a sì bá a tí ó ti kún fún àwọn ẹ̀ṣọ́ t’ó lágbára àti àwọn ògúnná

[9] Dájúdájú àwa máa ń jókòó síbẹ̀ ní àwọn ibùdó kan fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n ẹni t’ó bá jọ́rọ̀ gbọ́ lásìkò yìí, ó máa rí ògúnná t’ó ti lúgọ dè é

[10] Dájúdájú àwa kò sì mọ̀ bóyá aburú ni wọ́n gbà lérò pẹ̀lú àwọn t’ó wà lórí ilẹ̀ tàbí Olúwa wọn gbèrò ìmọ̀nà fún wọn

[11] Dájúdájú àwọn ẹni rere wà nínú wa. Àwọn mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn tún wà nínú wa. A wà lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

[12] Dájúdájú àwa mọ àmọ̀dájú pé àwa kò lè mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Àwa kò sì lè sá mọ́ Ọn lọ́wọ́

[13] Dájúdájú nígbà tí a gbọ́ nípa ìmọ̀nà (láti inú al-Ƙur’ān), a gbà á gbọ́. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Olúwa rẹ̀ gbọ́, kí ó má bẹ̀rù àdínkù (ẹ̀san rere) àti (àlékún) aburú

[14] Dájúdájú àwọn mùsùlùmí wà nínú wa. Àwọn arúfin náà wà nínú wa. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ’Islām, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ṣe àwárí ìmọ̀nà

[15] Ní ti àwọn arúfin, àwọn ni wọ́n máa jẹ́ igi ìkoná fún iná Jahanamọ.”

[16] Àti pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n dúró ṣinṣin lójú ọ̀nà (’Islām) ni, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní omi púpọ̀ mu

[17] Nítorí kí Á lè fi dán wọn wò ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Olúwa rẹ̀, Ó máa mú un wọ inú ìyà ìnira

[18] Dájúdájú àwọn mọ́sálásí ń jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fi pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu

[19] Dájúdájú nígbà tí ẹrúsìn Allāhu dìde dúró t’ó ń pe Allāhu, àwọn àlùjànnú fẹ́ẹ̀ máa dìfún-ùn-ùnfún lọ́dọ̀ rẹ̀ (láti tẹ́tí sí al-Ƙur’ān)

[20] Sọ pé: "Olúwa mi ni mò ń pè. Àti pé èmi kò níí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Un

[21] Sọ pé: "Dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ìnira àti ìmọ̀nà fun yín

[22] Sọ pé: "Dájúdájú èmi, kò sí ẹnì kan t’ó lè gbà mí là lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì rí ibùsásí kan lẹ́yìn Rẹ̀

[23] Àfi (kí n̄g ṣe) ìkédé (t’ó wá) láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ (t’Ó fi rán mi). Ẹnikẹ́ni t’ó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ń bẹ fún un. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé

[24] (Aláìgbàgbọ́ kò níí yé ṣàì gbàgbọ́) títí di ìgbà tí wọ́n yóò fi rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. Nígbà náà, wọn yóò mọ ta ni ó lẹ jùlọ ní alárànṣe, tí ó sì kéré jùlọ ní òǹkà

[25] Sọ pé: "Èmi kò mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín ti súnmọ́ tàbí Olúwa mi yóò fún un ní àkókò (t’ó jìnnà)

[26] Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, kò sì fi (ìmọ̀) ìkọ̀kọ̀ Rẹ̀ han ẹnì kan

[27] àyàfi ẹni tí Ó ṣàlẹ́ṣà t’ó jẹ́ Òjísẹ́. Dájúdájú Ó ń mú ẹ̀ṣọ́ kan rìn níwájú Òjíṣẹ́ náà àti lẹ́yìn rẹ̀

[28] nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn pé wọ́n ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa wọn. Àti pé Allāhu fi ìmọ̀ rọkiri ká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì ṣọ́ òǹkà gbogbo n̄ǹkan

Ẹni tí a fi wé

Surah 73

[1] Ìwọ olùdaṣọbora

[2] Dìde (kírun) ní òru àyàfi fún ìgbà díẹ̀

[3] Lo ìlàjì rẹ̀ tàbí dín díẹ̀ kù nínú rẹ̀

[4] Tàbí fi kún un. Kí o sì ké al-Ƙur’ān ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́

[5] Dájúdájú Àwa máa gbé ọ̀rọ̀ t’ó lágbára fún ọ

[6] Dájúdájú ìdìde kírun lóru, ó wọnú ọkàn jùlọ, ó sì dára jùlọ fún kíké (al-Ƙur’ān)

[7] Dájúdájú iṣẹ́ púpọ̀ wà fún ọ ní ọ̀sán

[8] Rántí orúkọ Olúwa rẹ. Kí o sì da ọkàn kọ Ọ́ pátápátá

[9] Olúwa ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, mú Un ní Aláfẹ̀yìntì

[10] Kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Pa wọ́n tì ní ìpatì t’ó rẹwà

[11] Fi Mí dá àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn ọlọ́rọ̀. Kí o sì lọ́ra fún wọn fún ìgbà díẹ̀

[12] Dájúdájú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ àti Iná Jẹhīm ń bẹ lọ́dọ̀ Wa

[13] Oúnjẹ háfunháfun àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro (tún wà fún wọn)

[14] Ní ọjọ́ tí ilẹ̀ àti àwọn àpáta yóò máa mì tìtì pẹ̀lú ohùn igbe líle. Àwọn àpáta sì máa di yanrìn tí wọ́n kójọ tí wọ́n túká

[15] Dájúdájú Àwa rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ si yín (tí ó jẹ́) olùjẹ́rìí lórí yín gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ sí Fir‘aon

[16] Ṣùgbọ́n Fir‘aon yapa Òjíṣẹ́ náà. A sì gbá a mú ní ìgbámú líle

[17] Tí ẹ̀yin bá ṣàì gbàgbọ́, báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe bẹ̀rù ọjọ́ kan t’ó máa mú àwọn ọmọdé hewú

[18] Sánmọ̀ sì máa fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú rẹ̀. Àdéhùn Rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa ṣẹ

[19] Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà kan tọ̀ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀

[20] Dájúdájú Olúwa rẹ mọ̀ pé dájúdájú ìwọ ń dìde kírun fún ohun t’ó kéré sí ìlàta méjì òru tàbí ìlàjì rẹ̀ tàbí ìlàta rẹ̀. Igun kan nínú àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu l’Ó ń ṣòdíwọ̀n òru àti ọ̀sán. Ó sì mọ̀ pé ẹ kò lè ṣọ́ ọ. Nítorí náà, Ó ti dá a padà sí fífúyẹ́ fun yín. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fun yín) nínú al-Ƙur’ān. Ó mọ̀ pé àwọn aláìsàn yóò wà nínú yín. Àwọn mìíràn sì ń rìrìn àjò lórí-ilẹ̀, tí wọ́n ń wá nínú oore Allāhu. Àwọn mìíràn sì ń jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fun yín) nínú rẹ̀. Ẹ kírun (ọ̀ran-an-yàn). Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára. Ohunkóhun tí ẹ bá tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín nínú ohun rere, ẹ̀yin yóò bá a lọ́dọ̀ Allāhu ní ohun rere àti ní ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀san. Ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run

Ẹni tí a fi aṣọ bora

Surah 74

[1] Ìwọ olùdaṣọbora

[2] Dìde kí o ṣèkìlọ̀

[3] Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún

[4] Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́

[5] Òrìṣà ni kí o jìnnà sí

[6] Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà

[7] Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún

[8] Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde

[9] ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira

[10] tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́

[11] Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan

[12] Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá

[13] àti àwọn ọmọkúnrin t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀

[14] Mo sì ṣe ayé nírọ̀rùn fún un gan-an

[15] Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún

[16] Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa

[17] Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)

[18] Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀)

[19] Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu

[20] Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu

[21] Lẹ́yìn náà, ó wò sùn

[22] Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí

[23] Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìn dà, ó sì ṣègbéraga

[24] Ó sì wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́

[25] Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara

[26] Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr

[27] Kí l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ iná Saƙọr

[28] (Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì

[29] Ó máa jó awọ ara di dúdú

[30] (Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀

[31] Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: "Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?" Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ̀ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara

[32] Ẹ gbọ́! Allāhu búra pẹ̀lú òṣùpá

[33] Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ

[34] Ó tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́

[35] Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) t’ó tóbi

[36] (Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara

[37] Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn

[38] Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́

[39] Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún

[40] Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

[41] nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé

[42] Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr

[43] Wọn yóò wí pé: "Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni

[44] Àwa kò sì sí nínú àwọn t’ó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù

[45] Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ

[46] Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́

[47] títí ikú fi dé bá wa

[48] Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní

[49] Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí

[50] bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ t’ó ń sá lọ

[51] t’ó sá fún kìnìhún

[52] Rárá, ńṣe ni ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān)

[53] Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni

[54] Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí

[55] Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kó rántí rẹ̀

[56] Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì làforíjìn

Àjíǹde

Surah 75

[1] Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú Ọjọ́ Àjíǹde

[2] Mo tún ń búra pẹ̀lú ẹ̀mí t’ó máa dára rẹ̀ lẹ́bi

[3] Ṣé ènìyàn lérò pé A ò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni

[4] Rárá o. A lágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba

[5] Ṣùgbọ́n ènìyàn gbèrò láti pe (Ọjọ́ Àjíǹde) t’ó ń bẹ níwájú rẹ̀ nírọ́

[6] Ó ń bèèrè pé: "Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde

[7] Nígbà tí ojú bá kọ mọ̀nà

[8] àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn

[9] àti (nígbà) tí A bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn

[10] ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: "Níbo ni ibùsásí wà

[11] Rárá, kò sí ibùsásí

[12] Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn

[13] Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun t’ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun t’ó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀)

[14] Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀

[15] ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá

[16] Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e

[17] Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀

[18] Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀

[19] Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ

[20] Ẹ gbọ́! Ńṣe l’ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé

[21] Ẹ sì ń pa ọ̀run tì

[22] Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú)

[23] Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò

[24] Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́

[25] (Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé Wọ́n máa fi aburú kan òhun

[26] Ẹ gbọ́! Nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò

[27] A sì máa sọ pé: "Ǹjẹ́ ọlọ́fọ̀ pípè kan wà bí (tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)

[28] Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé

[29] Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun

[30] Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn

[31] Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun

[32] Ṣùgbọ́n ó pe òdodo nírọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i

[33] Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí

[34] Ègbé ni fún ọ, ègbé ni sẹ́

[35] Lẹ́yìn náà, ègbé ni fún ọ, ègbé sì sẹ́

[36] Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni

[37] Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni

[38] Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é t’ó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn

[39] (Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti inú rẹ̀, akọ àti abo

[40] Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí

Àkókò

Surah 76

[1] Ṣebí àkókò kan nínú ìgbà ti ré kọjá lórí ènìyàn tí (ènìyàn) kò jẹ́ kiní kan tí wọ́n ń dárúkọ

[2] Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara àtọ̀ t’ó ròpọ̀ mọ́ra wọn (láti ara ọkùnrin àti obìnrin), kí Á lè dán an wò. A sì ṣe é ní olùgbọ́, olùríran

[3] Dájúdájú A fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n; Ó lè jẹ́ olùdúpẹ́, ó sì lè jẹ́ aláìmoore

[4] Dájúdájú Àwa pèsè àwọn ẹ̀wọ̀n, àjàgà àti Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́

[5] Dájúdájú àwọn ẹni rere, wọn yóò máa mu omi kan nínú ife. Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (omi náà) ni káfúrà

[6] Omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan ni, tí àwọn ẹrúsìn Allāhu yóò máa mu, tí wọn yó sì máa mú un ṣàn jáde dáadáa (sí ibi tí wọ́n bá fẹ́)

[7] Wọ́n ń mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Wọ́n sì ń páyà ọjọ́ kan, tí aburú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa fọ́nká gan-an

[8] Tòhun ti bí wọ́n ṣe ní ìfẹ́ sí (ọrọ̀ tó), wọ́n ń fún mẹ̀kúnnù, ọmọ òrukàn àti ẹrú ní oúnjẹ jẹ

[9] (Wọ́n sì ń sọ pé:) "Nítorí Ojú rere Allāhu (nìkan) l’a fi ń fun yín ní oúnjẹ; àwa kò sì gbèrò ẹ̀san tàbí ìdúpẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ yín

[10] Dájúdájú àwa ń páyà ní ọ̀dọ̀ Olúwa wa ọjọ́ kan tí (ẹ̀dá yóò) fajú ro kókó

[11] Nítorí náà, Allāhu yóò ṣọ́ wọn níbi aburú ọjọ́ yẹn. Ó sì máa fún wọn ni ìtutù ojú àti ìdùnnú

[12] Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san Ọgbà Ìdẹ̀ra àti aṣọ àlárì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù

[13] Wọn yóò máa rọ̀gbọ̀ kú sórí àwọn ibùsùn wọn. Wọn kò sì níí rí òòrùn tàbí òtútù

[14] Àwọn òòji (inú Ọgbà Ìdẹ̀ra) yóò súnmọ́ wọn. A sì máa mú àwọn esò ibẹ̀ súnmọ́ àrọ́wọ́tó wọn ní ti sísúnmọ́

[15] Àti pé wọn yóò máa gbé ife ìmumi ńlá tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà àti àwọn ife ìmumi kékeré tí ó jẹ́ aláwo káà kiri ọ̀dọ̀ wọn

[16] Ife aláwo tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà ni (wọ́n). A sì ṣe wọ́n níwọ̀n-níwọ̀n (tí ó ṣe wẹ́kú ohun tí wọ́n fẹ́ mu)

[17] Àti pé wọn yóò máa fún wọn ní ife ọtí kan mu nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (ọtí náà) ni atalẹ̀

[18] Nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra (wọn yóò tún máa mu) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí À ń pè ní omi salsabīl

[19] Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí gbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. Nígbà tí ìwọ bá sì rí wọn, ìwọ yóò kà wọ́n kún òkúta olówó iyebíye tí wọ́n tàn kalẹ̀

[20] Nígbà tí ìwọ bá sì wo ibẹ̀ yẹn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), ìwọ yóò rí ìdẹ̀ra àti ọlá t’ó tóbi

[21] Aṣọ ara wọn ni aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláwọ̀ ewéko àti aṣọ alágbàáà. A sì máa fi ẹ̀gbà-ọwọ́ onífàdákà ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́. Olúwa wọn yó sì fún wọn ní ohun mímu mímọ́ mu

[22] Dájúdájú èyí jẹ́ ẹ̀san fun yín. Iṣẹ́ yín sì já sí ọpẹ́

[23] Dájúdájú Àwa l’A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ díẹ̀díẹ̀

[24] Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Má ṣe tẹ̀lé ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí aláìmoore kan nínú wọn

[25] Rántí orúkọ Olúwa rẹ ní àárọ̀ àti ní àṣálẹ́

[26] Àti ní òru, forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní òru fún ìgbà pípẹ́

[27] Dájúdájú àwọn wọ̀nyí fẹ́ràn ayé. Wọ́n sì ń pa ọjọ́ t’ó wúwo tì sẹ́yìn wọn

[28] Àwa l’A ṣẹ̀dá wọn. A sì ṣe wọ́n ní alágbára. Nígbà tí A bá sì fẹ́, A óò fi irú wọn (mìíràn) pààrọ̀ wọn ní ti ìpààrọ̀

[29] Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà tọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀

[30] Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (kiní kan) àfi tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n

[31] Ó máa fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ rẹ̀. (Ní ti) àwọn alábòsí, Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n

Àwọn Ońṣẹ́

Surah 77

[1] Allāhu búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé

[2] Ó búra pẹ̀lú àwọn ìjì atẹ́gùn t’ó ń jà

[3] Ó búra pẹ̀lú àwọn atẹ́gùn t’ó ń tú èṣújò ká

[4] Ó búra pẹ̀lú àwọn t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́

[5] Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́)

[6] (Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀

[7] Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fun yín kúkú máa ṣẹlẹ̀

[8] Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́

[9] àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada

[10] àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù

[11] àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ, (Àkókò náà ti dé nìyẹn)

[12] Ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná

[13] Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni

[14] Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà

[15] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[16] Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí

[17] Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun)

[18] Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀

[19] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[20] Ṣé A ò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí

[21] Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)

[22] títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ)

[23] A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀). (Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá t’ó dára

[24] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[25] Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun t’ó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn

[26] (ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú

[27] A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fun yín ní omi dídùn mu

[28] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[29] Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè nírọ́

[30] Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta

[31] Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná

[32] Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè t’ó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì

[33] (Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn

[34] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[35] Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀

[36] A ò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá

[37] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[38] Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ

[39] Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò

[40] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[41] Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú

[42] àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́

[43] Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[44] Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere)

[45] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[46] Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín

[47] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[48] Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun

[49] Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

[50] Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀

Ìròyìn

Surah 78

[1] Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná

[2] Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni

[3] èyí tí wọ́n ń yapa ẹnu sí

[4] Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀

[5] Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀

[6] Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí

[7] àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)

[8] A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo)

[9] A ṣe oorun yín ní ìsinmi

[10] A tún ṣe alẹ́ ní ìbora

[11] A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu

[12] A tún mọ sánmọ̀ méje t’ó lágbára sókè yín

[13] A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ t’ó ń tàn gbòlà

[14] Àti pé A sọ omi t’ó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò

[15] nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde

[16] pẹ̀lú àwọn ọgbà t’ó kún digbí fún n̄ǹkan oko

[17] Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan

[18] (Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ

[19] Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn

[20] Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná

[21] Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà

[22] (Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ

[23] Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ

[24] Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀

[25] àyàfi omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀

[26] (Ó jẹ́) ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn)

[27] Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́

[28] Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́ gan-an

[29] Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan

[30] Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fun yín bí kò ṣe ìyà

[31] Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)

[32] Àwọn ọgbà àti èso àjàrà

[33] àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí

[34] àti ife ọtí t’ó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn)

[35] Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀

[36] (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn)

[37] (Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀

[38] Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ t’ó ṣe wẹ́kú

[39] Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà)

[40] Dájúdájú A fi ìyà t’ó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fun yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà)

Àwọn tó ń fà jáde

Surah 79

[1] Allāhu búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́

[2] Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[3] Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀

[4] Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà

[5] Ó tún búra pẹ̀lú àwọn mọlāika t’ó ń ṣètò ilé ayé

[6] Ní ọjọ́ tí ìfọn àkọ́kọ́ fún òpin ayé máa mi gbogbo ayé tìtì pẹ̀lú ohùn igbe

[7] Ìfọn kejì fún Àjíǹde sì máa tèlé e

[8] Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn

[9] Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ

[10] Wọn yóò wí pé: "Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)

[11] Ṣé nígbà tí a ti di eegun t’ó kẹfun tán

[12] Wọ́n wí pé: "Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni t’ó pè é nírọ́)

[13] Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni

[14] Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa

[15] Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ

[16] (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonífojì mímọ́, Tuwā

[17] Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-àlà

[18] Kí o sì sọ pé: "Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí

[19] Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, kí o páyà (Rẹ̀)

[20] Ó sì fi àmì t’ó tóbi hàn án

[21] (Àmọ́) ó pè é lópùrọ́. Ó sì yapa rẹ̀

[22] Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó)

[23] Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì

[24] Ó sì wí pé: "Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ

[25] Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́)

[26] Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni t’ó ń páyà (Allāhu)

[27] Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ

[28] Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé t’ó gún régé

[29] Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde

[30] Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn

[31] Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀

[32] Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin

[33] Ìgbádùn ni fun yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín

[34] Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé

[35] ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun t’ó ṣe níṣẹ́

[36] Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni t’ó ríran

[37] Nítorí náà, ní ti ẹni t’ó bá tayọ ẹnu-àlà

[38] tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé

[39] dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀)

[40] Ní ti ẹni tí ó bá páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀)

[41] dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀)

[42] Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: "Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀

[43] Ọ̀nà wo ni ìwọ lè fi ní (ìmọ̀) ìrántí rẹ̀ ná

[44] Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà

[45] Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni t’ó ń páyà rẹ̀

[46] Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò lò tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan lọ (nílé ayé)

Ó dojú rú

Surah 80

[1] (Ànábì s.a.w.) fajú ro, ó sì pẹ̀yìn dà

[2] nítorí pé afọ́jú wá bá a

[3] Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)

[4] tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní

[5] Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀

[6] òun ni ìwọ tẹ́tí sí

[7] Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)

[8] Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, t’ó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú)

[9] tí ó sì ń páyà (Allāhu)

[10] ìwọ kò sì kọbi ara sí i

[11] Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí

[12] Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀

[13] (Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé

[14] A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́

[15] ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika)

[16] àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere

[17] Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ

[18] Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀

[19] Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀

[20] Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un

[21] Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè

[22] Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde

[23] Ẹ gbọ́, ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un

[24] Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀

[25] Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀

[26] Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn

[27] A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀

[28] àti èso àjàrà àti kànnáfùrù

[29] àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù

[30] àti àwọn ọgbà t’ó kún fún igi

[31] àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde)

[32] (Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín

[33] Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀

[34] ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀

[35] àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀

[36] àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀

[37] Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn t’ó máa tó o ó rán

[38] Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀

[39] Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú

[40] Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀

[41] Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀

[42] Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀

Ìdìtẹ́palẹ̀

Surah 81

[1] Nígbà tí Wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù

[2] àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri

[3] àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù)

[4] àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì

[5] àti nígbà tí Wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ

[6] àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná

[7] àti nígbà tí Wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)

[8] àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé

[9] ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún

[10] àti nígbà tí Wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀

[11] àti nígbà tí Wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè

[12] àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò

[13] àti nígbà tí Wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo)

[14] (nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi)

[15] Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ t’ó ń yọ ní alẹ́, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán

[16] (ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ t’ó ń rìn lọ rìn bọ̀, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn

[17] Mo tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ

[18] Mo tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀

[19] Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé

[20] alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá

[21] ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán

[22] Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad s.a.w.) kì í ṣe wèrè

[23] Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere

[24] Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i)

[25] Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀

[26] Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ

[27] Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá

[28] (Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé

[29] Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá

Ìlà

Surah 82

[1] Nígbà tí sánmọ̀ bá fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ

[2] àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri

[3] àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn

[4] àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè

[5] (nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀)

[6] Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé

[7] Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn

[8] Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́

[9] Ní ti òdodo, ńṣe l’ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́

[10] Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín

[11] (Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá

[12] Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́

[13] Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn

[14] Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm

[15] Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san

[16] Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀

[17] Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san

[18] Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san

[19] (Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu

Ìdẹ́rùbà

Surah 83

[1] Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù

[2] àwọn (òǹtajà) t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún

[3] nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù

[4] Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde

[5] ní Ọjọ́ ńlá kan

[6] Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde nàró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá

[7] Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni ibi kúkú wà nínú Sijjīn

[8] Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Sijjīn

[9] Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn)

[10] Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́

[11] àwọn t’ó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́

[12] Kò sì sí ẹni t’ó ń pè é nírọ́ àfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀

[13] Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: "Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)

[14] Rárá kò rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ibi l’ó jọba lórí ọkàn wọn

[15] Ní ti òdodo, dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn

[16] Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm

[17] Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè nírọ́

[18] Bẹ́ẹ̀ ni. Dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn

[19] Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ ‘illiyyūn

[20] Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn)

[21] Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i

[22] Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn

[23] Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn

[24] Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn

[25] Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí

[26] Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn

[27] Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà)

[28] (Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu

[29] Dájúdájú àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín

[30] Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn adẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́

[31] Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí

[32] Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: "Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà

[33] Àwa kò sì rán wọn níṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn

[34] Nítorí náà, ní òní àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín

[35] Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn

[36] Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)

Ṣíṣẹ́

Surah 84

[1] Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ

[2] ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ –

[3] àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú

[4] ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo

[5] – ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ – (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)

[6] Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀

[7] Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀

[8] láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn

[9] Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú

[10] Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀

[11] láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun

[12] Ó sì máa wọ inú Iná t’ó ń jò fòfò

[13] Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé)

[14] Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni)

[15] Rárá (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀

[16] Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwòǹpapa

[17] Mo tún búra pẹ̀lú òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀

[18] Mo tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀)

[19] Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan

[20] Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo

[21] Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀

[22] Rárá, ńṣe ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é nírọ́

[23] Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn)

[24] Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro

[25] Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin ń bẹ fún wọn

Àwọn Ìràwọ̀

Surah 85

[1] (Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀

[2] Ó tún búra pẹ̀lú ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn

[3] Ó tún búra pẹ̀lú olùjẹ́rìí àti ohun t’ó jẹ́rìí sí

[4] A ṣẹ́bi lé àwọn t’ó gbẹ́ kòtò (iná)

[5] (ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò)

[6] (Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀

[7] Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo

[8] Kò sì sí kiní kan tí wọ́n torí rẹ̀ jẹ wọ́n níyà bí kò ṣe pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ọlọ́pẹ́

[9] Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan

[10] Dájúdájú àwọn t’ó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná t’ó ń jò sì wà fún wọn

[11] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá

[12] Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le

[13] Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde)

[14] Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá)

[15] Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ

[16] Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́

[17] Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ

[18] (ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd

[19] Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo nírọ́

[20] Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn

[21] Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé

[22] tí ó wà nínú wàláà tí À ń ṣọ́

Ìràwọ̀ Òwúrọ̀

Surah 86

[1] (Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ

[2] Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Tọ̄riƙ

[3] Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni)

[4] Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika)

[5] Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀

[6] Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi t’ó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́

[7] Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin

[8] Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀

[9] ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́

[10] Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un

[11] Allāhu búra pẹ̀lú sánmọ̀ t’ó ń rọ òjò ní ọdọọdún

[12] Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ t’ó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso)

[13] Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́)

[14] Kì í sì ṣe àwàdà

[15] Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an

[16] Èmi náà sì ń déte gan-an

[17] Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀

Olú Ọ̀gá Ògo

Surah 87

[1] Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ

[2] Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba

[3] Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà

[4] Ẹni tí Ó mú koríko tútù (hù) jáde

[5] Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ t’ó dúdú

[6] Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé

[7] Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun t’ó pamọ́

[8] Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ

[9] Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò

[10] Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí

[11] Olórí-burúkú sì máa takété sí i

[12] (Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná t’ó tóbi

[13] Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà)

[14] Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn rẹ̀) ti jèrè

[15] Ó tún rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun

[16] Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé

[17] Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé

[18] Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́

[19] tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā

Ìbòrí-lẹ́ṣẹ́

Surah 88

[1] Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun t’ó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ

[2] Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn

[3] Oníṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni wọ́n nílé ayé)

[4] Wọ́n máa wọ inú Iná t’ó gbóná janjan (ní ọ̀run)

[5] Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi gbígbóná mu

[6] Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ

[7] Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi

[8] Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn

[9] nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀

[10] (Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga

[11] Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀

[12] Omi ìṣẹ́lẹ̀rú t’ó ń ṣàn wà nínú rẹ̀

[13] Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀

[14] àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn)

[15] àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn

[16] àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká

[17] Nítorí náà, ṣé wọn kò wo ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni

[18] àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè

[19] àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀)

[20] àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ ní gban̄sasa

[21] Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí

[22] Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn

[23] àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́

[24] Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà t’ó tóbi jùlọ

[25] Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà

[26] Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn

Àfẹ̀mọ́júmọ́

Surah 89

[1] Allāhu búra pẹ̀lú àfẹ̀mọ́júmọ́

[2] Ó tún búra pẹ̀lú àwọn òru mẹ́wàá kan

[3] Ó tún búra pẹ̀lú méjì àti ẹyọ

[4] Ó tún búra pẹ̀lú òru nígbà tí ó bá lọ (tí ó bá dé)

[5] Ǹjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè

[6] Ṣé o ò rí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād

[7] (ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán

[8] àwọn tí A ò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú

[9] Àti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonífojì

[10] àti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)

[11] (Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn t’ó tayọ ẹnu-àlà nínú ìlú

[12] Wọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀

[13] Olúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí

[14] Dájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá)

[15] Nítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti pọ́n mi lé

[16] Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi

[17] Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn

[18] Àti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ

[19] Ẹ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ

[20] Àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀

[21] Rárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (t’ó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ)

[22] (tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

[23] ní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un

[24] Ó máa wí pé: "Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi

[25] Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́)

[26] Ẹnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é)

[27] Ìwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀

[28] padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú

[29] Nítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi

[30] Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi

Ìlú

Surah 90

[1] Èmi (Allāhu) búra pẹ̀lú ìlú yìí

[2] Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀)

[3] (Mo tún) búra pẹ̀lú òbí àti ohun t’ó bí

[4] Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro

[5] Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni

[6] Ó (sì) ń wí pé: "Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì s.a.w)

[7] Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni

[8] Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un

[9] Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)

[10] A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n

[11] Kò sì mú àkàbà ìgbàlà gùn

[12] Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ àkàbà ìgbàlà

[13] (Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú

[14] Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi

[15] (Ó lè jẹ́) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí

[16] tàbí mẹ́kùnnú, ẹni ilẹ̀ẹ́lẹ̀

[17] Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe

[18] Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún

[19] Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì

[20] A máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá

Oòrùn

Surah 91

[1] (Allāhu) búra pẹ̀lú òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀

[2] Ó tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn)

[3] Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru

[4] Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀

[5] Ó tún búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n

[6] Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀

[7] Ó tún búra pẹ̀lú ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba

[8] Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n

[9] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè

[10] Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù

[11] Ìjọ Thamūd pe òdodo nírọ́ nípa ìtayọ ẹnu-àlà wọn

[12] (Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa)

[13] Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: "(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀)

[14] Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn

[15] (Ẹni t’ó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn

Òru

Surah 92

[1] (Allāhu) búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú

[2] Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n

[3] Ó tún búra pẹ̀lú Ẹni tí Ó dá akọ àti abo

[4] Dájúdájú iṣẹ́ yín, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni

[5] Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu)

[6] (tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní òdodo

[7] A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un

[8] Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni t’ó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run

[9] (tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní irọ́

[10] A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un

[11] Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá já bọ́ (sínú Iná)

[12] Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà

[13] Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé

[14] Nítorí náà, Mo ti fi Iná eléjò fòfò kìlọ̀ fun yín

[15] Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú

[16] ẹni tí ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i

[17] Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu)

[18] ẹni t’ó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀)

[19] Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni

[20] bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ

[21] Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rẹ̀)

Àwọn Wákàtí Òwúrọ̀

Surah 93

[1] (Allāhu búra pẹ̀lú) ìyálẹ̀ta

[2] Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú

[3] Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ

[4] Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé lọ

[5] Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i

[6] Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé

[7] Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́

[8] Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀

[9] Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí)

[10] Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn)

[11] Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde

Ìtura

Surah 94

[1] Ṣé A ò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí

[2] A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ

[3] èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn. àmọ́ tí onítọ̀ún padà gba ’Islām ìbáà jẹ́ pé ó gbà á ní òwúrọ̀

[4] A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ

[5] Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira

[6] Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́

[7] Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ọ̀kan), gbìyànjú (òmíràn)

[8] Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí

Ọ̀pọ̀tọ́

Surah 95

[1] Allāhu búra pẹ̀lú èso tīn àti èso zaetūn

[2] Ó tún búra pẹ̀lú àpáta Sīnīn

[3] Ó tún búra pẹ̀lú ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí

[4] Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí t’ó dára jùlọ

[5] Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná)

[6] Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn

[7] Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)

[8] Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni

Ẹ̀jẹ̀ Dídì

Surah 96

[1] Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá

[2] Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì

[3] Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ

[4] Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn

[5] Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n

[6] Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-àlà

[7] nítorí pé ó ríra rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀

[8] Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá

[9] Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń kọ̀

[10] fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun

[11] Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

[12] tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)

[13] Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i

[14] Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni)

[15] Bẹ́ẹ̀ ni (Allāhu ń rí i.) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí i lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná)

[16] àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀

[17] Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀

[18] Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná

[19] Rárá o, má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o súnmọ́ (Allāhu)

Àṣẹ

Surah 97

[1] Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì

[2] Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Òru Abiyì

[3] Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù lọ

[4] Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan

[5] Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́

Ẹ̀rí Tó Yanju

Surah 98

[1] Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn kò níí kúrò nínú àìgbàgbọ́ wọn títí di ìgbà tí ẹ̀rí t’ó yanjú yó fi máa dé ọ̀dọ̀ wọn

[2] Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu yó (sì) máa ké àwọn tákàdá mímọ́

[3] Àwọn ìwé òfin t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sì wà nínú rẹ̀

[4] Àwọn tí A fún ní tírà kò sì di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ẹ̀rí t’ó yanjú dé bá wọn

[5] Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu (kí wọ́n jẹ́) olùṣe-àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un, olùdúró déédé. Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀

[6] Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (wọ̀nyí) nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá t’ó burú jùlọ

[7] Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí), tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá t’ó dára jùlọ

[8] Ẹ̀san wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Àwọn náà yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Olúwa rẹ̀

Ìsẹ̀lẹ̀

Surah 99

[1] Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀

[2] àti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù t’ó wúwo nínú rẹ̀ jáde

[3] ènìyàn yó sì wí pé: "Kí l’ó mú un

[4] Ní ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe)

[5] Nítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀)

[6] Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n

[7] Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i

[8] Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i

Àwọn Agẹṣinjagun

Surah 100

[1] Allāhu búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń sáré t’ó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun

[2] Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá)

[3] Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù

[4] Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè

[5] Wọ́n tún bẹ́ gìjà papọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ sáààrin àkójọ ọ̀tá

[6] Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀

[7] Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn

[8] Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé

[9] Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun t’ó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde)

[10] tí wọ́n sì tú ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá

[11] dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn

Àjàkálẹ̀-àrùn

Surah 101

[1] Àkókò ìjáyà

[2] Kí ni Àkókò ìjáyà

[3] Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà

[4] (Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta

[5] àwọn àpáta yó sì dà bí òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù

[6] Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n

[7] ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó yọ́nú sí

[8] Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́

[9] Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀

[10] Kí sì ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀

[11] (Òhun ni) Iná gbígbóná gan-an

Ìdíje nínú ayé

Surah 102

[1] Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín

[2] títí ẹ fi wọ inú sàréè

[3] Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀

[4] Lẹ́yìn náà, ní òdodo láìpẹ́ ẹ máa mọ̀

[5] Bẹ́ẹ̀ ni, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀)

[6] Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm

[7] Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa rí i ní àrídájú

[8] Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí)

Ọjọ́ tí ń kọjá lọ

Surah 103

[1] Allāhu búra pẹ̀lú àkókò ìrọ̀lẹ́ ayé

[2] Dájúdájú ènìyàn wà nínú òfò

[3] Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ òdodo láààrin ara wọn, tí wọ́n sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ sùúrù láààrin ara wọn

Olùbanijẹ́

Surah 104

[1] Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni

[2] ẹni tí ó kó owó jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fẹ́sìn)

[3] Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé)

[4] Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni

[5] Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Hutọmọh

[6] (Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (t’ó ń jò geregere)

[7] èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ

[8] Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá

[9] (Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná)

Erin

Surah 105

[1] Ṣé o ò rí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ìjọ elérin ni

[2] Ṣé kò sọ ète wọn di òfo bí

[3] Ó sì rán àwọn ẹyẹ níkọ̀níkọ̀ sí wọn

[4] Wọ́n ń jù wọ́n ní òkúta amọ̀ (t’ó ti gbaná sára)

[5] Ó sì sọ wọ́n di bíi èrúnrún koríko àjẹkù gbígbẹ

Quréshì

Surah 106

[1] (Ìkẹ́ ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún ìdílé Ƙuraeṣ láti wà papọ̀ nínú ààbò

[2] (Ìkẹ́ ni sẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún wọn láti wà papọ̀ nínú ààbò lórí ìrìn-àjò ní ìgbà òtútù àti ìgbà ooru

[3] Nítorí náà, kí wọ́n jọ́sìn fún Olúwa Ilé (Ka‘bah) yìí

[4] Ẹni tí Ó fún wọn ní jíjẹ (ní àsìkò) ebi. Ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nínú ìpáyà

Àwọn Ìṣeun Rere Kéékèèké

Surah 107

[1] Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san nírọ́

[2] Ìyẹn ni ẹni t’ó ń lé ọmọ-òrukàn dànù

[3] Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù

[4] Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) t’ó ń kírun; kò túmọ̀ sí “ohun t’ó ń run ènìyàn”. Àmọ́ ìtúmọ̀ “ìrun” ni “ohun t’ó ń run ẹ̀ṣẹ̀ olùkírun” nítorí pé tí olùkírun bá ti ṣe àlùwàlá ni ó ti ṣan gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ tí ó ti fi àwọn oríkèé ara rẹ̀ ṣe ṣíwájú. Bákan náà

[5] àwọn t’ó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀

[6] àwọn t’ó ń ṣe ṣekárími

[7] àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn)

Ọ̀pọ̀lọpọ̀

Surah 108

[1] Dájúdájú Àwa fún ọ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore

[2] Nítorí náà, kírun fún Olúwa rẹ, kí o sì gúnran (fún Un)

[3] Dájúdájú, ẹni t’ó ń bínú rẹ, òun ni kò níí lẹ́yìn

Àwọn Káfírì

Surah 109

[1] Sọ pé: "Ẹ̀yin aláìgbàgbọ́

[2] Èmi kò níí jọ́sìn fún ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún

[3] Ẹ̀yin náà kò jọ́sìn fún Ẹni tí mò ń jọ́sìn fún

[4] Èmi kò níí jọ́sìn fún ohun tí ẹ jọ́sìn fún sẹ́

[5] Ẹ̀yin náà kò kú jọ́sìn fún Ẹni tí mò ń jọ́sìn fún

[6] Tiyín ni ẹ̀sìn yín, tèmi sì ni ẹ̀sìn mi

Ìrànlọ́wọ́

Surah 110

[1] Nígbà tí àrànṣe Allāhu (lórí ọ̀tá ẹ̀sìn) àti ṣíṣí ìlú (Mọ́kkah) bá ṣẹlẹ̀

[2] tí o sì rí àwọn ènìyàn tí wọ́n wọnú ẹ̀sìn Allāhu níjọníjọ

[3] nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ. Kí o sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà

Ọwọ́ Iná

Surah 111

[1] Ọwọ́ Abu-Lahab méjèèjì ti ṣòfò. Òun náà sì ṣòfò

[2] Àwọn dúkìá rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ìyẹn, àwọn ọmọ rẹ̀) kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ (níbi ìyà)

[3] Ó sì máa wọ inú Iná eléjò fòfò

[4] Àti ìyàwó rẹ̀, aláàárù-igi-ìṣẹ́pẹ́ ẹlẹ́gùn-ún, (ó máa wọná)

[5] Igbà-ọ̀pẹ pọ̀npọ̀nràn máa wà ní ọrùn rẹ̀ (nínú Iná)

Ìwà Mímọ́

Surah 112

[1] Sọ pé: "Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo

[2] Allāhu ni Aṣíwájú (tí ẹ̀dá ní bùkátà sí, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn)

[3] Kò bímọ. Wọn kò sì bí I

[4] Kò sì sí ẹnì kan tí ó jọ Ọ́." èyí ni a mọ̀ sí “rọbbu-ssamọ̄wāt wal-’ard wa mọ̄ baenahumọ̄”. Ìdí nìyí tí a ò fi túmọ̀ “Allāhu” sí “Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá kò fẹ́ẹ̀ sí ìtúmọ̀ tí a fọkàn balẹ̀ sí fún ọ̀rọ̀-orúkọ ńlá náà “Allāhu” àfi lílo ọ̀rọ̀-orúkọ kan èyí tí àwọn Yorùbá máa ń lò ní ọjọ́un àná fún “Ọlọ́hun”. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sí máa mú àríyànjiyàn lọ́wọ́. Nítorí náà

Àfẹ̀mọ́júmọ́

Surah 113

[1] Sọ pé: "Mo sá di Olúwa òwúrọ̀ kùtùkùtù

[2] níbi aburú ohun tí Ó dá

[3] àti níbi aburú òru nígbà tí ó bá ṣóòkùn

[4] àti níbi aburú àwọn (òpìdán) t’ó ń fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú àwọn ońdè

[5] àti níbi aburú onílara nígbà tí ó bá ṣe ìlara

Aráyé

Surah 114

[1] Sọ pé: "Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn

[2] Ọba àwọn ènìyàn

[3] Ọlọ́hun àwọn ènìyàn

[4] níbi aburú (Èṣù) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni t’ó bá dárúkọ Allāh)

[5] (Èṣù ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn

[6] (Èṣù náà) wà nínú àlùjànnú àti ènìyàn