Back to Languages
Yoruba - Chapter 25
Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Verse 1
Ibukun ni fun Eni ti O so oro-ipinya (ohun t’o n sepinya laaarin ododo ati iro) kale fun erusin Re nitori ki o le je olukilo fun gbogbo eda
Verse 2
(Oun ni) Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile. Ko mu eni kan kan ni omo. Ko si akegbe fun Un ninu ijoba (Re). O da gbogbo nnkan. O si yan odiwon (irisi, isemi ati ayanmo) fun un niwon-niwon
Verse 3
(Awon alaigbagbo) so awon kan di olohun leyin Allahu. Won ko si le da kini kan. A si da won ni. Won ko si ni ikapa inira tabi anfaani kan fun emi ara won. Ati pe won ko ni ikapa lori iku, isemi ati ajinde
Verse 4
Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Ki ni eyi bi ko se adapa iro kan ti o da adapa re (mo Allahu), ti awon eniyan miiran si ran an lowo lori re.” Dajudaju (awon alaigbagbo) ti gbe abosi ati iro de
Verse 5
Won tun wi pe: “Akosile alo awon eni akoko, ti o sadako re ni. Ohun ni won n pe fun un ni owuro ati ni asale.”
Verse 6
So pe: "Eni ti O mo ikoko ti n be ninu awon sanmo ati ile l’O so o kale. Dajudaju Oun ni O n je Alaforijin, Asake-orun
Verse 7
Won tun wi pe: “Ki lo mu Ojise yii, t’o n jeun, t’o n rin ninu awon oja? Nitori ki ni Won ko se so molaika kan kale fun un ki o le je olukilo pelu re
Verse 8
Tabi (nitori ki ni) won ko se ju apoti-oro kan sodo re, tabi ki o ni ogba oko kan ti o ma maa je ninu re?” Awon alabosi si tun wi pe: “Ta ni e n tele bi ko se okunrin eleedi kan.”
Verse 9
Wo bi won se fun o ni awon afiwe (buruku)! Nitori naa, won ti sina; won ko si le mona
Verse 10
Ibukun ni fun Eni ti (o je pe) bi O ba fe, O maa soore t’o dara ju iyen fun o. (O si maa je) awon ogba ti awon odo yoo maa san ni isale re. O si maa fun o ni awon aafin kan
Verse 11
Nse ni won pe Akoko naa niro. A si ti pese Ina t’o n jo sile de enikeni ti o ba pe Akoko naa niro
Verse 12
Nigba ti (Ina naa) ba ri won lati aye kan ti o jinna, won yo si maa gbo ohun ibinu ati kikun (re)
Verse 13
Nigba ti Won ba si ju won si aye t’o ha gadigadi ninu (Ina), ti won de owo won mo won lorun, won yo si maa kigbe iparun nibe
Verse 14
(A o so pe): “E ma se kigbe iparun eyo kan, e kigbe iparun lopolopo.”
Verse 15
So pe: “Nje iyen lo loore julo ni tabi Ogba Idera gbere, eyi ti A se ni adehun fun awon oluberu Allahu. O si je esan ati ikangun rere fun won
Verse 16
Ohunkohun ti won ba n fe wa fun won ninu re. Olusegbere ni won (ninu re). (Eyi) je adehun ti won ti toro lodo Oluwa re
Verse 17
Ati pe (ranti) ojo ti (Allahu) yoo ko awon aborisa ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu jo, (Allahu) yo si so pe: “Se eyin l’e si awon erusin Mi wonyi lona ni tabi awon ni won sina (funra won)?”
Verse 18
Won wi pe: “Mimo ni fun O! Ko to fun wa lati mu awon kan ni alatileyin leyin Re. Sugbon Iwo l’O fun awon ati awon baba won ni igbadun, titi won fi gbagbe Iranti. Won si je eni iparun.”
Verse 19
(Allahu so pe): “Dajudaju awon orisa ti pe eyin aborisa ni opuro nipa ohun ti e n so (pe olusipe ni won). Ni bayii won ko le gbe iya Ina kuro fun yin, won ko si le ran yin lowo. Enikeni ti o se abosi (ebo sise) ninu yin, A si maa fun un ni iya t’o tobi to wo.”
Verse 20
A ko ran awon Ojise nise ri siwaju re afi ki won jeun, ki won si rin ninu oja. A ti fi apa kan yin se adanwo fun apa kan, nje e maa se suuru bi? Oluwa Re si n je Oluriran
Verse 21
Awon ti ko reti ipade Wa (ni orun) wi pe: “Won ko se so awon molaika kale fun wa, tabi ki a ri Oluwa wa (soju nile aye)? Dajudaju won ti segberaga ninu emi won. Won si ti tayo enu-ana ni itayo-enu ala t’o tobi
Verse 22
(Ranti) ojo ti won yoo ri awon molaika, ko nii si iro idunnu fun awon elese ni ojo yen. (Awon molaika) yo si so pe: “Eewo, eewo (ni iro idunnu fun eyin elese).”
Verse 23
Ati pe A maa wa sibi ohun ti won se nise, A si maa so o di eruku afedanu
Verse 24
Awon ero inu Ogba Idera, ni ojo yen, (ogba won) maa loore julo ni ibugbe. O si maa dara julo ni ibusinmi
Verse 25
Ati pe (ranti) ojo ti sanmo yo faya pelu awon esujo funfun. A si maa so awon molaika kale taara
Verse 26
Ijoba ododo ti ojo yen n je ti Ajoke-aye. O si je ojo kan ti o maa nira fun awon alaigbagbo
Verse 27
(Ranti) ojo ti alabosi yoo je ika owo re mejeeji, o si maa wi pe: "Yee! Emi iba ti to ona kan (naa) pelu Ojise naa
Verse 28
Egbe mi o, yee! Emi iba ti mu lagbaja ni ore ayo
Verse 29
Dajudaju o ti si mi lona kuro nibi Iranti leyin ti o de ba mi. Dajudaju Esu n je adani-dasoro fun omoniyan
Verse 30
Ojise naa so pe: “Oluwa mi dajudaju awon eniyan mi ti pa al-Ƙur’an yii ti.”
Verse 31
Bayen ni A se awon kan ninu awon elese ni ota fun Anabi kookan. Oluwa re si to ni Afinimona ati Alaranse
Verse 32
Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Won ko se so al-Ƙur’an kale fun un ni apapo ni ee kan naa?” (A so o kale diedie) bayen nitori ki A le fi rinle sinu okan re. A si ke e fun o diedie
Verse 33
Won ko nii mu apeere kan wa fun o (bi ibeere lati fi tako o) afi ki A mu ododo (iyen, al-ƙur’an) ati alaye t’o dara julo wa fun o (lori re)
Verse 34
Awon ti A maa ko jo lo sinu ina Jahanamo ni idojubole, awon wonyen ni aye won buru julo. Won si sina julo
Verse 35
Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira. A tun se arakunrin re, Harun, ni amugbalegbee fun un
Verse 36
A si so pe: “Eyin mejeeji, e lo sodo ijo t’o pe awon ayah Wa niro. A si pa ijo naa run patapata
Verse 37
(Ranti) ijo (Anabi) Nuh. Nigba ti won pe awon Ojise ni opuro, A te won ri sinu omi. A si se won ni ami kan fun awon eniyan. A si ti pese iya eleta-elero sile de awon alabosi
Verse 38
(Ranti) awon ijo ‘Ad, ijo Thamud, ijo Rass ati awon opolopo iran miiran (t’o n be) laaarin won
Verse 39
Ikookan won ni A fun ni awon apejuwe (nipa awon t’o tako ododo). Ikookan won si ni A parun patapata
Verse 40
Ati pe dajudaju won koja ni ilu ti A ro ojo buruku le lori. Se won ki i ri i ni? Rara, nse ni won ko reti Ajinde
Verse 41
Nigba ti won ba si ri o, ko si ohun ti won yoo fi o se bi ko se yeye. (Won a wi pe): “Se eyi ni eni ti Allahu gbe dide ni Ojise
Verse 42
O ma fee seri wa kuro nibi awon olohun wa, ti ki i ba se pe a taku sori re.” Laipe won maa mo eni ti o sina julo nigba ti won ba ri iya
Verse 43
So fun mi nipa eni ti o so ife-inu re di olohun re! Nitori naa, se iwo maa je alaabo fun un ni (nibi iya)
Verse 44
Tabi iwo n ro pe dajudaju opolopo won n gboran tabi pe won n se laakaye? Ki ni won na, bi ko se bi agutan. Won wule sina julo
Verse 45
Se o o ri (ise) Oluwa re ni, bi O se fe okunkun owuro loju (soju sanmo)? Ti O ba fe ni, iba da a duro sibe. Leyin naa, A fi oorun se atoka si bibe okunkun
Verse 46
Leyin naa, A (fi imole oorun) mu okunkun (kuro nita) wa si odo Wa ni mimu diedie (ki ojumo le mo)
Verse 47
Ati pe Oun ni Eni ti O se oru ni ibora fun yin. (O se) oorun ni isinmi (fun yin). O tun se osan ni asiko itusita (fun wiwa ije-imu)
Verse 48
Oun si ni Eni t’’O n ran ategun ni iro-idunnu siwaju ike Re. A si so omi mimo kale lati sanmo
Verse 49
nitori ki A le fi so oku ile di aye ile ati nitori ki A le fun eran-osin ati opolopo eniyan ninu awon ti A da ni omi mu
Verse 50
Dajudaju A ti pin omi yii laaarin won nitori ki won le ranti (ike Oluwa won). Sugbon opolopo eniyan ko (lati ranti) afi aimoore
Verse 51
Ti o ba je pe A ba fe ni, A iba gbe olukilo kan dide ninu ilu kookan
Verse 52
Nitori naa, ma se tele awon alaigbagbo. Ki o si fi (al-Ƙur’an) ja won ni ogun t’o tobi
Verse 53
Oun ni Eni ti O mu awon odo meji san kiri. Eyi (ni omi) t’o dun gan-an. Eyi si (ni omi) iyo t’o moro. O fi gaga si aarin awon mejeeji. (O si) se e ni eewo ponnbele (fun won lati ko inira ba eda)
Verse 54
Oun ni Eni ti O seda abara lati inu omi. O se ibatan ebi ati ibatan ana fun un, Oluwa re si n je Alagbara
Verse 55
Won n josin fun leyin Allahu ohun ti ko le se won ni anfaani, ti ko si le ko inira ba won. Alaigbagbo je oluranlowo (fun Esu) lati tako Oluwa re
Verse 56
A ko si ran o nise tayo ki o je oniroo-idunnu ati olukilo
Verse 57
So pe: “Emi ko beere owo-oya kan lowo yin lori re afi eni ti o ba fe mu ona (daadaa) to lo si odo Oluwa re.”
Verse 58
Gbarale Alaaye ti ko nii ku. Se afomo pelu idupe fun Un. Allahu si to ni Alamotan nipa ese awon erusin Re
Verse 59
(Oun ni) Eni ti O seda awon sanmo, ile ati awon nnkan t’o n be laaarin mejeeji laaarin ojo mefa. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. Ajoke-aye ni, nitori naa, beere nipa Re (lodo Re nitori pe, O je) Alamotan
Verse 60
Nigba ti won ba so fun won pe: “E fori kanle fun Ajoke-aye.” Won a wi pe: “Ki ni Ajoke-aye? Se ki a fori kanle fun ohun ti o n pa wa lase re ni?” (Ipepe naa) si mu won lekun ni sisa-seyin
Verse 61
Ibukun ni fun Eni ti O se awon irawo sinu sanmo. O tun se oorun ati osupa ni imole sinu re
Verse 62
Oun ni Eni ti O se oru ati osan ni itelentele (ti ikini yato si ikeji) nitori eni ti o ba gbero lati se iranti (Allahu) tabi ti o ba gbero idupe (fun Un)
Verse 63
Awon erusin Ajoke-aye ni awon t’o n rin jeeje lori ile. Nigba ti awon ope ba si doju oro ko won, won yoo so oro alaafia
Verse 64
(Awon ni) awon t’o n lo oru won ni iforikanle ati iduro-kirun fun Oluwa won
Verse 65
(Awon ni) awon t’o n so pe: “Oluwa wa, gbe iya ina Jahanamo kuro fun wa. Dajudaju iya re je iya ainipekun
Verse 66
Dajudaju o buru ni ibugbe ati ibuduro
Verse 67
Awon ti o je pe nigba ti won ba nawo, won ko na ina-apa, won ko si sahun; (inawo won) wa laaarin iyen ni iwontun-wonsi
Verse 68
(Awon ni) awon ti ko pe olohun miiran mo Allahu. Won ko pa emi ti Allahu se (pipa re) ni eewo afi ni ona eto. Ati pe won ko se zina. Enikeni ti o ba se (aburu) yen, o maa pade (iya) ese
Verse 69
A oo se iya ni ilopo fun un ni Ojo Ajinde. O si maa se gbere ninu re ni eni yepere
Verse 70
Afi eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni Allahu yoo fi ise rere ropo ise aburu won (iyen, nipa ironupiwada won). Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
Verse 71
Enikeni ti o ba ronu piwada, ti o si se ise rere, (ki o mo) pe dajudaju o n ronu piwada patapata sodo Allahu ni
Verse 72
(Awon ni) awon ti ko jerii eke. Ti won ba si koja nibi ibaje, won a koja pelu aponle
Verse 73
(Awon ni) awon ti o je pe ti won ba fi awon ayah Oluwa won seranti fun won, won ko da lule bi aditi ati afoju
Verse 74
(Awon ni) awon t’o n so pe: “Oluwa wa, ta wa ni ore itutu-oju lati ara awon iyawo wa ati awon omo wa. Ki O si se wa ni asiwaju fun awon oluberu (Re).”
Verse 75
Awon wonyen, ipo giga (ninu Ogba Idera) ni A maa fi san won ni esan nitori pe won se suuru. Ikini ati sisalamo ni A oo fi maa pade won ninu re
Verse 76
Olusegbere ni won ninu re. O dara ni ibugbe ati ibuduro
Verse 77
So pe: "Oluwa mi ko ka yin kun ti ki i ba se adua yin. E kuku ti pe (awon ayah Re) niro. Laipe o si maa di iya ainipekun (fun yin)