Back to Languages

    Yoruba - Chapter 26

    Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

    Verse 1

    To sin mim

    Verse 2

    Iwonyi ni awon ayah Tira t’o n yanju oro eda

    Verse 3

    Nitori ki ni o se maa para re pe won ko je onigbagbo ododo

    Verse 4

    Ti A ba fe, A maa so ami kan kale fun won lati sanmo. Awon orun won ko si nii ye teriba fun un

    Verse 5

    Ko si iranti kan ti o maa de ba won ni titun lati odo Ajoke-aye afi ki won je olugbunri kuro nibe

    Verse 6

    Dajudaju won ti pe (ayah Wa) niro. Nitori naa, awon iro ohun ti won n fi se yeye n bo wa ba won

    Verse 7

    Se won ko ri ile pe meloo meloo ninu gbogbo orisirisi nnkan alapon-onle ti A mu hu jade lati inu re

    Verse 8

    Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo

    Verse 9

    Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

    Verse 10

    (Ranti) nigba ti Oluwa re pe (Anabi) Musa pe: "Lo ba ijo alabosi

    Verse 11

    ijo Fir‘aon (ki o si so fun won) pe 'Se won ko nii beru (Allahu) ni

    Verse 12

    O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro

    Verse 13

    O si maa je inira fun mi (ti won ba pe mi ni opuro). Ahon mi ko si ja gaaraga. Nitori naa, ranse si Harun

    Verse 14

    Ati pe mo ni ese kan lorun lodo won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi

    Verse 15

    (Allahu) so pe: "Rara (won ko le pa o). Nitori naa, ki eyin mejeeji mu awon ami (ise iyanu) Wa lo (ba won). Dajudaju Awa n be pelu yin; A n gbo (oro yin)

    Verse 16

    Eyin mejeeji, e lo ba Fir‘aon. Ki e so fun un pe: 'Dajudaju awa ni Ojise Oluwa gbogbo eda

    Verse 17

    (A n so fun o) pe ki o je ki awon omo ’Isro’il maa ba wa lo

    Verse 18

    (Fir‘aon) wi pe: “Se ki i se ni aarin wa ni a ti to o ni kekere ni, ti o si gbe ni odo wa fun odun pupo ninu isemi aye re

    Verse 19

    O si se ise owo re ti o se (si wa). Iwo si wa ninu awon alaimoore.”

    Verse 20

    (Anabi Musa) so pe: "Mo se e nigba naa nigba ti mo wa ninu awon alaimokan ni

    Verse 21

    Mo si sa fun yin nigba ti mo beru yin. Nitori naa, Allahu ti ta mi lore ipo Anabi. O si se mi ni (okan) ninu awon Ojise

    Verse 22

    Ati pe iyen ni idera ti o n se iregun re le mi lori. Pe o so awon omo ’Isro’il di eru (nko)

    Verse 23

    Fir‘aon wi pe: “Ki ni Oluwa gbogbo eda?”

    Verse 24

    (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni)

    Verse 25

    (Fir‘aon) wi fun awon t’o wa ni ayika re pe: “Se e e gbo oro (t’o n so ni)?”

    Verse 26

    (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko.”

    Verse 27

    (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju Ojise yin eyi ti won ran si yin, were ma ni.”

    Verse 28

    (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa ibuyo oorun, ibuwo oorun ati ohunkohun t’o n be laaarin awon mejeeji, ti e ba maa n se laakaye.”

    Verse 29

    (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju ti o ba fi le josin fun olohun kan yato si mi, dajudaju mo maa so o di ara awon elewon.”

    Verse 30

    (Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe mo mu kini kan t’o yanju wa fun o nko?”

    Verse 31

    (Fir‘aon) wi pe: “Mu un wa nigba naa ti iwo ba wa ninu awon olododo.”

    Verse 32

    Nitori naa, o ju opa re sile, o si di ejo ponnbele

    Verse 33

    O tun fa owo re yo sita, o si di funfun fun awon oluworan

    Verse 34

    (Fir‘aon) wi fun awon ijoye ti won wa ni ayika re pe: “Dajudaju eyi ni onimo nipa idan pipa

    Verse 35

    O fe ko yin kuro lori ile yin ni. Ki ni ohun ti e maa mu wa ni imoran?”

    Verse 36

    Won wi pe: "Da oun ati arakunrin re duro na, ki o si ran awon akonijo si awon ilu

    Verse 37

    (pe) ki gbogbo onimo nipa idan pipa wa ba o

    Verse 38

    Won si ko awon opidan jo ni asiko ti won fi adehun si ni ojo ti (gbogbo ilu) ti mo

    Verse 39

    Won si wi fun awon eniyan pe: "Se eyin maa ko jo (sibe) bi

    Verse 40

    Nitori ki a le tele awon opidan ti o ba je pe awon ni olubori

    Verse 41

    Nigba ti awon opidan de, won wi fun Fir‘aon pe: “Nje owo-oya kan wa fun wa, ti o ba je pe awa gan-an la je olubori?”

    Verse 42

    (Fir‘aon) wi pe: “Bee ni, dajudaju nigba naa e maa wa ninu awon alasun-unmo (mi).”

    Verse 43

    (Anabi) Musa so fun won pe: “E ju ohun ti e fe ju sile.”

    Verse 44

    Won si ju awon okun won ati opa won sile. Won wi pe: “Pelu ogo Fir‘aon, dajudaju awa, awa ni olubori.”

    Verse 45

    Nigba naa, (Anabi) Musa ju opa re sile. O si n gbe ohun ti won pa niro kale mi kalokalo

    Verse 46

    Nitori naa, ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan wo lule, ti won fori kanle (fun Allahu)

    Verse 47

    Won so pe: "A gbagbo ninu Oluwa gbogbo eda

    Verse 48

    Oluwa (Anabi) Musa ati Harun

    Verse 49

    Fir‘aon wi pe: “E gba A gbo siwaju ki ng to yonda fun yin! Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Laipe e n bo wa mo. Dajudaju mo maa ge owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Leyin naa, dajudaju mo maa kan gbogbo yin mogi.”

    Verse 50

    (Awon opidan) so pe: “Ko si inira fun wa! Dajudaju awa yo si fabo si odo Oluwa wa

    Verse 51

    Dajudaju awa n reti pe Oluwa wa yoo se aforijin awon asise wa fun wa nitori pe awa je eni akoko (ti o je) onigbagbo ododo.”

    Verse 52

    A fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Mu awon erusin Mi rin ni oru (nitori pe) dajudaju won yoo lepa yin.”

    Verse 53

    Fir‘aon si ran awon akonijo sinu awon ilu (lati so pe)

    Verse 54

    Dajudaju awon (omo ’Isro’il) wonyi, ijo perete die ni won

    Verse 55

    Ati pe dajudaju won ti se ohun t’o n bi wa ninu

    Verse 56

    Dajudaju gbogbo wa ni ki a si wa tifura-tifura

    Verse 57

    Nitori naa, A mu (ijo Fir‘aon) jade kuro ninu awon ogba oko ati iseleru omi

    Verse 58

    ati awon apoti-oro ati ibujokoo aponle

    Verse 59

    Bayen (loro ri). A si jogun re fun awon omo ’Isro’il

    Verse 60

    Won si lepa won ni asiko ti oorun yo

    Verse 61

    Nigba ti ijo mejeeji rira won, awon ijo (Anabi) Musa so pe: “Dajudaju won yoo le wa ba.”

    Verse 62

    (Anabi) Musa so pe: “Rara, dajudaju Oluwa mi n be pelu mi. O si maa fi ona mo mi.”

    Verse 63

    A si fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Fi opa re na agbami okun.” (O fi na a). O si pin (si ona mejila). Ipin kookan si da bi apata nla

    Verse 64

    A si mu ijo keji (iyen, ijo Fir‘aon) sunmo ibe yen

    Verse 65

    A gba (Anabi) Musa ati gbogbo awon t’o n be pelu re la patapata

    Verse 66

    Leyin naa, A te ijo keji ri (sinu agbami)

    Verse 67

    Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo

    Verse 68

    Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

    Verse 69

    Ka iroyin (Anabi) ’Ibrohim fun won

    Verse 70

    Nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: “Ki ni nnkan ti e n josin fun na?”

    Verse 71

    Won wi pe: “A n josin fun awon ere kan ni. A o si nii ye taku ti won lorun.”

    Verse 72

    (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Nje won n gbo oro yin nigba ti e ba n pe won

    Verse 73

    Tabi (se) won le se yin ni oore tabi won le fi inira kan yin?”

    Verse 74

    Won wi pe: “Rara o! A ba awon baba wa, ti won n se bee ni”

    Verse 75

    (Anabi ’Ibrohim) so pe: " E so fun mi, ki ni nnkan ti e n josin fun

    Verse 76

    eyin ati awon baba yin isaaju

    Verse 77

    Dajudaju awon ni ota fun mi ayafi Oluwa gbogbo eda

    Verse 78

    (Oun ni) Eni ti O seda mi. Nitori naa, O maa fi ona mo mi

    Verse 79

    Eni t’O n fun mi ni jije, t’O n fun mi ni mimu

    Verse 80

    Ati pe nigba ti ara mi ko ba ya, Oun l’O n wo mi san

    Verse 81

    Eni ti O maa pa mi, leyin naa, O maa so mi di alaaye

    Verse 82

    Eni ti mo ni ireti si pe O maa fori awon asise mi jin mi ni Ojo Esan

    Verse 83

    Oluwa mi, ta mi ni ore ipo Anabi. Da mi po mo awon eni rere

    Verse 84

    Je ki awon t’o n bo leyin (mi) maa soro mi pelu daadaa

    Verse 85

    Se mi ni okan ninu awon olujogun Ogba Idera

    Verse 86

    Ki O si forijin baba mi. Dajudaju o je okan ninu awon olusina

    Verse 87

    Ma se doju ti mi ni ojo ti won yoo gbe eda dide

    Verse 88

    Ojo ti dukia kan tabi awon omo ko nii sanfaani

    Verse 89

    Ayafi eni ti o ba de odo Allahu pelu okan mimo

    Verse 90

    A maa mu Ogba Idera sunmo awon oluberu (Allahu)

    Verse 91

    Won si maa fi ina Jehim han awon olusina

    Verse 92

    won yo si so fun won pe: “Nibo ni nnkan ti e n josin fun wa?”

    Verse 93

    (Nnkan ti e n josin fun) leyin Allahu, se won le ran yin lowo tabi se won le ran ara won lowo

    Verse 94

    Won si maa taari gbogbo won sinu Ina; awon ati esu won

    Verse 95

    ati awon omo ogun ’Iblis patapata

    Verse 96

    (Awon alaigbagbo), nigba ti won ba n ba ara won jiyan ninu Ina, won a wi pe

    Verse 97

    A fi Allahu bura, dajudaju awa kuku ti wa ninu isina ponnbele

    Verse 98

    nigba ti a fi yin se akegbe fun Oluwa gbogbo eda

    Verse 99

    Ko si ohun ti o si wa lona bi ko se awon (esu) elese

    Verse 100

    Ko si si awon olusipe kan fun wa

    Verse 101

    Ko tun si ore imule kan (fun wa)

    Verse 102

    Ti o ba je pe ipada si ile aye wa fun wa ni, nigba naa awa iba wa ninu awon onigbagbo ododo

    Verse 103

    Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

    Verse 104

    Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

    Verse 105

    Ijo (Anabi) Nuh pe awon Ojise ni opuro

    Verse 106

    Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Nuh, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni

    Verse 107

    Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

    Verse 108

    Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

    Verse 109

    Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

    Verse 110

    Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi.”

    Verse 111

    Won wi pe: “Se ki a gba o gbo nigba ti o je pe awon eniyan yepere l’o n tele o!?”

    Verse 112

    O so pe: “Emi ko nimo si ohun ti won n se (leyin mi)

    Verse 113

    Ko si isiro-ise won lodo eni kan bi ko se lodo Oluwa mi, ti o ba je pe e ba fura

    Verse 114

    Emi ko si nii le awon onigbagbo ododo danu

    Verse 115

    Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele.”

    Verse 116

    Won wi pe: “Dajudaju ti iwo Nuh ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa ju loko.”

    Verse 117

    O so pe: “Oluwa mi, dajudaju awon eniyan mi ti pe mi ni opuro

    Verse 118

    Nitori naa, sedajo taara laaarin emi ati awon. Ki o si la emi ati awon t’o wa pelu mi ninu awon onigbagbo ododo.”

    Verse 119

    A la oun ati awon t’o wa pelu re ninu oko oju-omi t’o kun keke

    Verse 120

    Leyin naa, A te awon t’o seku ri sinu omi

    Verse 121

    Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

    Verse 122

    Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

    Verse 123

    Awon iran ‘Ad pe awon Ojise ni opuro

    Verse 124

    Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Hud, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni

    Verse 125

    Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

    Verse 126

    Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

    Verse 127

    Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

    Verse 128

    Se e oo maa ko ile nla nla si awon aye giga (ki e le) maa fi awon olurekoja sefe

    Verse 129

    E si n ko awon ile nla nla bi eni pe e maa se gbere (nile aye yii)

    Verse 130

    Nigba ti e ba si gba (eniyan mu lati fiya je won), e n gba won mu ni igbamu alailoju-aanu

    Verse 131

    Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

    Verse 132

    E beru Eni ti O ran yin lowo pelu ohun ti e mo

    Verse 133

    O ran yin lowo pelu awon eran-osin ati awon omo

    Verse 134

    ati awon ogba oko pelu awon iseleru omi

    Verse 135

    Dajudaju emi n paya iya ojo nla fun yin.”

    Verse 136

    Won wi pe: “Bakan naa ni fun wa; yala o kilo fun wa tabi o o si ninu awon olukilo

    Verse 137

    Eyi ko je kini kan bi ko se iwa awon eni akoko

    Verse 138

    Won ko si nii je wa niya.”

    Verse 139

    Nitori naa, won pe e ni opuro. A si pa won run. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

    Verse 140

    Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

    Verse 141

    Awon iran Thamud pe awon Ojise ni opuro

    Verse 142

    Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Solih, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni

    Verse 143

    Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

    Verse 144

    Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

    Verse 145

    Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

    Verse 146

    Se ki won fi yin sile sibi nnkan ti o wa (nile aye) nibi yii (ninu igbadun aye, ki e je) olufokanbale

    Verse 147

    ninu awon ogba oko ati iseleru omi

    Verse 148

    ati oko irugbin pelu igi dabinu ti ogomo re tutu

    Verse 149

    E si n gbe awon ile sinu awon apata (gege bi) akose-mose

    Verse 150

    Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

    Verse 151

    Ki e si ma se tele ase awon alaseju

    Verse 152

    awon t’o n sebaje lori ile, ti won ko si se rere.”

    Verse 153

    Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi

    Verse 154

    Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Nitori naa, mu ami kan wa ti o ba wa ninu awon olododo.”

    Verse 155

    O so pe: “Eyi ni abo rakunmi kan. Omi wa fun ohun, omi si wa fun eyin naa ni ojo ti a ti mo

    Verse 156

    E ma se fi aburu kan kan an nitori ki iya ojo nla ma baa je yin.”

    Verse 157

    Won si gun un pa. Nitori naa, won si di alabaamo

    Verse 158

    Iya naa je won. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

    Verse 159

    Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

    Verse 160

    Ijo Lut pe awon Ojise ni opuro

    Verse 161

    Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Lut, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni

    Verse 162

    Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

    Verse 163

    Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

    Verse 164

    Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

    Verse 165

    Se awon okunrin ninu eda ni eyin okunrin yoo lo maa ba (fun adun ibalopo)

    Verse 166

    E si n pa ohun ti Oluwa yin da fun yin ti ninu awon iyawo yin! Ani se, ijo alakoyo ni eyin.”

    Verse 167

    Won wi pe: “Ti iwo Lut ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa le jade kuro ninu ilu.”

    Verse 168

    O so pe: "Dajudaju emi wa ninu awon olubinu si ise (aburu) owo yin

    Verse 169

    Oluwa mi, la emi ati awon eniyan mi nibi ohun ti won n se nise (aburu)

    Verse 170

    Nitori naa, A la oun ati awon eniyan re patapata

    Verse 171

    Afi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare)

    Verse 172

    Leyin naa, A pa awon yooku run

    Verse 173

    A ro ojo le won lori taara. Ojo awon ti A kilo fun si buru

    Verse 174

    Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

    Verse 175

    Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

    Verse 176

    Awon ara ’Aekah pe awon Ojise ni opuro

    Verse 177

    Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb, so pe: “Se eyin ko nii beru (Allahu) ni

    Verse 178

    Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

    Verse 179

    Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

    Verse 180

    Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

    Verse 181

    E won osuwon kun. Ki e si ma se wa ninu awon oludosuwonku

    Verse 182

    E fi iwon t’o to won nnkan

    Verse 183

    E ma se din nnkan awon eniyan ku. Ki e si ma se huwa aburu lori ile ni ti obileje

    Verse 184

    Ki e si beru Eni ti O da yin ati awon iran akoko.”

    Verse 185

    Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi

    Verse 186

    Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Ati pe a o ro o si kini kan bi ko se pe o wa ninu awon opuro

    Verse 187

    Nitori naa, je ki apa kan ninu sanmo ya lu wa mole, ti o ba wa ninu awon olododo.”

    Verse 188

    O so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa ohun ti e n se nise

    Verse 189

    Won si pe e ni opuro. Nitori naa, iya ojo esujo si je won. Dajudaju o je iya ojo nla

    Verse 190

    Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

    Verse 191

    Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

    Verse 192

    Dajudaju al-Ƙur’an, won so o kale ni lati odo Oluwa gbogbo eda

    Verse 193

    Molaika Jibril, olufokantan l’o so o kale

    Verse 194

    sinu okan re nitori ki o le wa ninu awon olukilo

    Verse 195

    pelu ede Larubawa ponnbele

    Verse 196

    Dajudaju (oro nipa re) ti wa ninu ipin-ipin Tira awon eni akoko

    Verse 197

    Se ko je ami kan fun won pe awon onimo (ninu) awon omo ’Isro’il nimo (si asoole nipa) re (ninu tira owo won)

    Verse 198

    Ti o ba je pe A so o kale fun apa kan awon elede miiran ni

    Verse 199

    ti o si ke e fun won, won ko nii gba a gbo ni ododo

    Verse 200

    Bayen ni A se mu (atako) wo inu okan awon elese

    Verse 201

    Won ko nii gba a gbo ni ododo titi won yoo fi ri iya eleta-elero

    Verse 202

    (Iya naa) yoo de ba won ni ojiji; won ko si nii fura

    Verse 203

    Nigba naa ni won yoo wi pe: "Nje won le lo wa lara bi

    Verse 204

    Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju

    Verse 205

    So fun Mi ti A ba fun won ni igbadun aye fun odun gbooro

    Verse 206

    Leyin naa, ki ohun ti A n se ni adehun fun won de ba won

    Verse 207

    Ohun ti A se ni igbadun fun won ko si nii ro won loro

    Verse 208

    A o si pa ilu kan run afi ki won ti ni awon olukilo

    Verse 209

    Iranti (de fun won se). Ati pe Awa ki i se alabosi

    Verse 210

    Ki i se awon esu ni won so (al-Ƙur’an) kale

    Verse 211

    Ko ye fun won. Won ko si lagbara re

    Verse 212

    Dajudaju A ti mu won takete si gbigbo re (lati oju sanmo)

    Verse 213

    Nitori naa, ma se pe olohun miiran mo Allahu, nitori ki iwo ma baa wa ninu awon ti A maa je niya

    Verse 214

    Ki o si kilo fun awon ebi re, t’o sunmo julo

    Verse 215

    Ki o si re apa re nile fun awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo

    Verse 216

    Ti won ba si yapa (ase) re, so pe: “Dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n se (nise aburu).”

    Verse 217

    Ki o si gbarale Alagbara, Asake-orun

    Verse 218

    Eni t’O n ri o nigba ti o n dide naro (fun irun kiki)

    Verse 219

    ati iyirapada re (fun rukuu ati iforikanle) laaarin awon oluforikanle

    Verse 220

    Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo

    Verse 221

    Se ki ng so eni ti awon esu n sokale wa ba

    Verse 222

    Won n sokale wa ba gbogbo awon opuro, elese

    Verse 223

    (Awon esu) n deti (si iro sanmo). Opolopo won si ni opuro

    Verse 224

    Awon elewi, awon olusina l’o n tele won

    Verse 225

    Se o o ri i pe gbogbo ogbun oro ni won n tenu bo ni

    Verse 226

    Ati pe dajudaju won n so ohun ti won ko nii se

    Verse 227

    Afi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se ise rere, ti won ranti Allahu ni opolopo, ti won si jaja gbara leyin ti won ti sabosi si won. Awon t’o sabosi si maa mo iru ikangun ti won maa gunle si