Back to Languages

    Yoruba - Chapter 42

    Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

    Verse 1

    Ha mim

    Verse 2

    ‘Aen sin ƙof

    Verse 3

    Bayen ni Allahu, Alagbara, Ologbon se n fi imisi ranse si iwo ati awon t’o siwaju re

    Verse 4

    TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. O ga, O tobi

    Verse 5

    Sanmo fee faya lati oke won (nipa titobi Allahu). Awon molaika si n se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won si n toro aforijin fun awon t’o wa lori ile. Gbo Mi, dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun

    Verse 6

    Awon t’o mu awon alatileyin kan leyin Re, Allahu si ni Alaabo lori won. Iwo si ko ni oluso lori won

    Verse 7

    Bayen ni A se fi al-Ƙur’an ranse si o ni ede Larubawa nitori ki o le fi se ikilo fun ’Ummul-Ƙuro (iyen, ara ilu Mokkah) ati enikeni ti o ba wa ni ayika re (iyen, ara ilu yooku), ati nitori ki o le fi se ikilo nipa Ojo Akojo, ti ko si iyemeji ninu re. Ijo kan yoo wa ninu Ogba Idera. Ijo kan yo si wa ninu Ina t’o n jo

    Verse 8

    Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se won ni ijo elesin eyo kan. Sugbon O n fi eni ti O ba fe sinu ike Re. Awon alabosi, ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won

    Verse 9

    Se won mu awon alaabo kan leyin Re ni? Allahu, Oun si ni Alaabo. Oun l’O n so awon oku di alaaye. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

    Verse 10

    Ohunkohun ti e ba yapa enu nipa re, idajo re di odo Allahu. Iyen ni Allahu, Oluwa mi. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni mo maa seri pada si (ni ti ironupiwada). oro Allahu ati idajo Re. Pelu agboye yii ayah yii je okan ninu awon ayah t’o n pa wa lase lati fi al-Ƙur’an ati sunnah Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) yanju awon oro iyapa-enu

    Verse 11

    (Oun ni) Olupileda awon sanmo ati ile. O seda awon obinrin fun yin lati ara yin. O tun seda awon abo eran-osin lati ara awon ako eran-osin. O n mu yin po si i (nipa iseda yin ni ako-abo). Ko si kini kan bi iru Re. Oun si ni Olugbo, Oluriran

    Verse 12

    TiRe ni awon kokoro apoti-oro awon sanmo ati ile. O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan

    Verse 13

    (Allahu) se ni ofin fun yin ninu esin (’Islam) ohun ti O pa ni ase fun (Anabi) Nuh ati eyi ti O fi ranse si o, ati ohun ti A pa lase fun (Anabi) ’Ibrohim, (Anabi) Musa ati (Anabi) ‘Isa pe ki e gbe esin naa duro. Ki e si ma se pin si ijo otooto ninu re. Wahala l’o je fun awon osebo nipa nnkan ti o n pe won si (nibi mimu Allahu ni okan soso). Allahu l’O n sesa eni ti O ba fe sinu esin Re (ti o n pe won si). O si n fi ona mo eni ti o ba n seri pada si odo Re (nipase ironupiwada)

    Verse 14

    (Awon osebo) ko si pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Ti ko ba je pe oro kan ti siwaju lodo Oluwa re (pe Oun yoo lo won lara) titi di gbedeke akoko kan ni, Won iba ti dajo laaarin won. Dajudaju awon ti A jogun Tira fun leyin won si tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa ’Islam

    Verse 15

    Nitori iyen, pepe (sinu ’Islam), ki o si duro sinsin gege bi Won se pa o lase. Ma si se tele ife-inu won. Ki o si so pe: "Mo gbagbo ninu eyikeyii Tira ti Allahu sokale. Won si pa mi lase pe ki ng se deede laaarin yin. Allahu ni Oluwa wa ati Oluwa yin. Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Ko si ija laaarin awa ati eyin. Allahu l’O si maa ko wa jo papo. Odo Re si ni abo eda.”

    Verse 16

    Awon t’o n ba (Anabi s.a.w.) ja nipa (esin) Allahu leyin igba ti awon eniyan ti gba fun un, eri won maa wo lodo Oluwa won. Ibinu n be lori won. Iya lile si wa fun won

    Verse 17

    Allahu ni Eni ti O so Tira (al-Ƙur’an) ati (ofin) osuwon (deede) kale pelu ododo. Ati pe ki l’o maa fi mo o pe o see se ki Akoko naa ti sunmo

    Verse 18

    Awon ti ko gba a gbo n wa a pelu ikanju. Awon t’o si gbagbo ni ododo n paya re. Won si mo pe dajudaju ododo ni. Kiye si i, dajudaju awon t’o n jiyan nipa Akoko naa ti wa ninu isina t’o jinna

    Verse 19

    Allahu ni Alaaanu fun awon erusin Re. O n se arisiki fun eni ti O ba fe. Oun si ni Alagbara, Abiyi

    Verse 20

    Enikeni ti o ba gbero lati gba eso (ise re ni) orun, A maa se alekun si eso re fun un. Enikeni ti o ba si gbero lati gba eso (ise re ni) aye, A maa fun un ninu re. Ko si nii si ipin kan kan fun un mo ni orun

    Verse 21

    Tabi won ni awon orisa kan t’o sofin (iborisa) fun won ninu esin, eyi ti Allahu ko yonda re? Ti ko ba je ti oro asoyan (pe A o nii kanju je won niya), Awa iba ti mu idajo wa laaarin won. Dajudaju awon alabosi, iya eleta-elero si wa fun won

    Verse 22

    O maa ri awon alabosi ti won yoo maa paya nitori ohun ti won se nise, ti o si maa ko le won lori. Awon t’o si gbagbo ni ododo, ti won se ise rere maa wa ni awon aye t’o rewa julo ninu Ogba Idera. Ohun ti won ba n fe maa wa fun won ni odo Oluwa won. Iyen, ohun ni oore ajulo t’o tobi

    Verse 23

    Iyen ni eyi ti Allahu fi n se iro idunnu fun awon erusin Re, awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. So pe: "Emi ko beere owo-oya lowo yin lori re bi ko se ife ebi.” Enikeni ti o ba se rere kan, A maa se alekun rere fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Olope

    Verse 24

    Tabi won n wi pe: "O da adapa iro mo Allahu ni?" Nitori naa, ti Allahu ba fe, O maa fi edidi di okan re pa. Ati pe Allahu yoo pa iro re. O si maa fi ododo rinle pelu oro Re. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda

    Verse 25

    Oun ni Eni t’O n gba ironupiwada awon erusin Re. O n se amojukuro nibi awon asise. O si mo ohun ti e n se nise

    Verse 26

    O n gba adua awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. O si n se alekun fun won ninu ola Re. Awon alaigbagbo, iya lile si wa fun won

    Verse 27

    Ti o ba je pe Allahu te arisiki sile regede fun awon erusin Re ni, won iba tayo enu-ala lori ile. Sugbon O n so (arisiki) ti O ba fe kale niwon-niwon. Dajudaju Oun ni Alamotan, Oluriran nipa awon erusin Re

    Verse 28

    Oun si ni Eni t’O n so omi ojo kale leyin igba ti won ti soreti nu. O si n fon ike Re ka. Oun si ni Alaabo, Eleyin

    Verse 29

    Ati pe ninu ami Re ni iseda awon sanmo, ile ati nnkan ti O fonka saaarin mejeeji ninu awon nnkan abemi. Oun si ni Alagbara lori ikojo won nigba ti O ba fe

    Verse 30

    Ohunkohun ti o ba kan yin ninu adanwo, ohun ti e fi owo ara yin fa ni. O si n samojukuro nibi opolopo

    Verse 31

    Eyin ko si nii mori bo (mo Allahu lowo) lori ile. Ko si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu

    Verse 32

    O tun wa ninu awon ami Re, awon oko oju-omi t’o n rin loju omi (t’o da) bi awon oke apata giga

    Verse 33

    Ti Allahu ba fe, O maa mu ategun naa duro, (awon oko oju-omi naa) si maa di ohun ti ko nii lo mo lori omi. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe

    Verse 34

    Ti Allahu ba fe, O maa mu ategun naa duro, (awon oko oju-omi naa) si maa di ohun ti ko nii lo mo lori omi. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe

    Verse 35

    Awon t’o n se atako si awon ayah Wa si maa mo pe ko si ibusasi kan fun won

    Verse 36

    Nitori naa, ohunkohun ti A ba fun yin, igbadun aye nikan ni. Ohun ti o wa lodo Allahu loore julo, o si maa seku titi laelae fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n gbarale Oluwa won

    Verse 37

    (Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o n jinna si awon ese nlanla ati awon iwa ibaje, ati (awon t’o je pe) nigba ti won ba binu, won yoo saforijin

    Verse 38

    (Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o jepe ti Oluwa won, ti won n kirun, oro ara won si je ijiroro laaarin ara won, won tun n na ninu arisiki ti A pese fun won

    Verse 39

    (Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon ti (o je pe) nigba ti won ba se abosi si won, won yoo gbesan won pada

    Verse 40

    Esan aburu si ni aburu bi iru re. Enikeni ti o ba si samojukuro, ti o tun satunse, esan re wa lodo Allahu. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alabosi

    Verse 41

    Dajudaju eni ti o ba si gbesan leyin ti won se abosi si i, awon wonyen (ti won sabosi si), ko si ibawi kan kan fun won

    Verse 42

    Awon ti ibawi wa fun ni awon t’o n sabosi si awon eniyan, ti won tun n tayo enu-ala lori ile lai letoo. Awon wonyen ni iya eleta-elero wa fun

    Verse 43

    Enikeni ti o ba se suuru, ti o tun saforijin, dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan

    Verse 44

    Enikeni ti Allahu ba si lona, ko tun si alaabo kan fun un mo leyin Re. O si maa ri awon alabosi nigba ti won ba ri Ina, won yoo wi pe: "Nje ona kan kan wa ti a le fi pada si ile aye

    Verse 45

    O si maa ri won ti A maa ko won lo sinu Ina; won yoo palolo lati ara iyepere, won yo si maa wo fin-in-fin. Awon t’o gbagbo ni ododo si maa so pe: "Dajudaju awon eni ofo ni awon t’o se emi ara won ati ara ile won ni ofo ni Ojo Ajinde." Kiye si i, dajudaju awon alabosi yoo wa ninu iya gbere

    Verse 46

    Ko si nii si alaabo kan fun won ti o maa ran won lowo leyin Allahu. Ati pe enikeni ti Allahu ba si lona, ko le si ona kan kan fun un

    Verse 47

    E jepe Oluwa yin siwaju ki ojo kan to de, ti ko si idapada kan fun un ni odo Allahu. Ko si ibusasi kan fun yin ni ojo yen. Ko si nii si olukoya kan fun yin

    Verse 48

    Nitori naa, ti won ba gbunri, A o ran o pe ki o je oluso fun won. Ko si kini kan t’o di dandan fun o bi ko se ise-jije. Ati pe dajudaju nigba ti A ba fun eniyan ni ike kan to wo lati odo Wa, o maa dunnu si i. Ti aburu kan ba si kan an nipase ohun ti owo won ti siwaju (ni ise aburu), dajudaju eniyan ni alaimoore

    Verse 49

    Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. O n seda ohun ti O ba fe. O n ta eni ti O ba fe lore omobinrin. O si n ta eni ti O ba fe ni lore omokunrin

    Verse 50

    Tabi ki O se won ni orisi meji; omokunrin ati omobinrin. O si n se eni ti O ba fe ni agan. Dajudaju Oun ni Onimo, Alagbara

    Verse 51

    Ko letoo fun abara kan pe ki Allahu ba a soro afi ki (oro naa) je imisi (isipaya mimo), tabi ki o je leyin gaga, tabi ki O ran Ojise kan (ti)

    Verse 52

    Bayen si ni A se fi imisi ranse si o ninu ase Wa. Iwo ko mo ki ni Tira ati igbagbo ododo tele (siwaju imisi naa),1 sugbon A se imisi naa ni imole kan ti A n fi se imona fun eni ti A ba fe ninu awon erusin Wa. Dajudaju iwo n pepe si ona taara (’Islam). 2 ise wiridi ni Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) maa n se ninu ogbun Hira siwaju ki o to di Anabi Olohun iro l’o fi pa. Idi ni pe

    Verse 53

    Ona Allahu, Eni ti ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n je tiRe. Gbo! Odo Allahu ni awon oro eda yoo pada si