Back to Languages
Yoruba - Chapter 69
Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Verse 1
Isele Ododo
Verse 2
Ki ni Isele Ododo
Verse 3
Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Isele Ododo
Verse 4
Awon ijo Thamud ati ijo ‘Ad pe Ipaya niro
Verse 5
Ni ti ijo Thamud, won fi igbe t’o tayo enu-ala pa won re
Verse 6
Ni ti ijo ‘Ad, won fi ategun lile t’o tayo enu-ala pa won re
Verse 7
O de e si won fun oru meje ati osan mejo lai dawo duro. O si maa ri ijo naa ti won ti ku sinu re bi eni pe kukute igi dabinu t’o ti luho ninu ni won
Verse 8
Nje o ri eni kan ninu won t’o se ku bi
Verse 9
Fir‘aon ati awon t’o siwaju re ati awon ilu ti won doju re bole de pelu awon asise
Verse 10
Won yapa Ojise Oluwa won. O si gba won mu ni igbamu alekun
Verse 11
Dajudaju nigba ti omi tayo enu-ala. A gbe yin gun oko oju-omi
Verse 12
Nitori ki A le fi se iranti fun yin ati nitori ki eti t’o n so nnkan le so o
Verse 13
Nigba ti won ba fon fere oniwo fun iku ni fifon eyo kan
Verse 14
ti won gbe ile ati apata soke, ti won si run mejeeji womuwomu ni rirun ee kan
Verse 15
ni ojo yen ni Isele maa sele
Verse 16
Ati pe sanmo yo faya perepere. O si maa fuye gege ni ojo yen
Verse 17
Awon molaika si maa wa ni awon egbeegbe re. Ati pe ni ojo yen, loke won, awon (molaika) mejo ni won maa ru Ite Oluwa re
Verse 18
Ni ojo yen, won yoo maa seri yin wa (fun isiro-ise). Ko si nii si asiri yin kan t’o maa pamo (fun Wa)
Verse 19
Nitori naa, ni ti eni ti won ba fun ni tira re ni owo otun re, o maa so pe: "E gba, e ka tira mi
Verse 20
Dajudaju emi ti mo amodaju pe dajudaju emi yoo ba isiro-ise mi pade
Verse 21
Nitori naa, o maa wa ninu isemi t’o maa yonu si
Verse 22
ninu Ogba Idera giga
Verse 23
Awon eso re (si) wa ni arowoto
Verse 24
E je, ki e si mu pelu igbadun nitori ohun ti e ti siwaju ninu awon ojo ti o ti re koja
Verse 25
Ni ti eni ti won ba si fun ni tira re ni owo osi re, o maa wi pe: "Haa! Ki won si ma fun mi ni tira mi! mejeeji lo maa sele si won nitori pe owo osi ni alaigbagbo maa ti bo inu igba-aya re bo si eyin re lati fi gba iwe ise re
Verse 26
Ati pe emi ko mo ohun ti isiro-ise mi je
Verse 27
Haa! Ki iku si je opin (oro eda)
Verse 28
Dukia mi ko si ro mi loro
Verse 29
Agbara mi si ti parun
Verse 30
E mu un, ki e de e ni owo mo orun
Verse 31
Leyin naa, inu ina Jehim ni ki e mu un wo
Verse 32
Leyin naa, inu ewon ti gigun re je aadorin gigun thar‘u ni ki e ki i si
Verse 33
Dajudaju oun ki i gbagbo ninu Allahu, Atobi
Verse 34
Ki i si gba eniyan niyanju lati bo awon mekunnu
Verse 35
Nitori naa, ko nii si ore imule kan fun un nibi yii ni oni
Verse 36
Ko si nii si ounje kan (fun un) bi ko se (ounje) awoyunweje
Verse 37
Ko si eni ti o maa je e bi ko se awon elese
Verse 38
Nitori naa, Emi n bura pelu ohun ti e n foju ri
Verse 39
ati ohun ti e o foju ri
Verse 40
Dajudaju al-Ƙur’an ni oro (ti A fi ran) Ojise, alapon-onle
Verse 41
Ki i se oro elewi. Ohun ti e gbagbo kere pupo
Verse 42
Ki i si se oro adabigba. Die le n lo ninu iranti
Verse 43
Won so o kale lati odo Oluwa gbogbo eda
Verse 44
Ti o ba je pe (Anabi) da adapa apa kan oro naa mo Wa ni
Verse 45
Awa iba gba a mu lowo otun
Verse 46
Leyin naa, Awa iba ja isan orun re
Verse 47
Ko si si eni kan ninu yin ti o maa gba a sile lowo (Wa)
Verse 48
Dajudaju (al-Ƙur’an) ni iranti fun awon oluberu (Allahu)
Verse 49
Dajudaju Awa si mo pe awon t’o n pe al-Ƙur’an niro wa ninu yin
Verse 50
Dajudaju al-Ƙur’an maa je abamo fun awon alaigbagbo
Verse 51
Dajudaju al-Ƙur’an ni ododo t’o daju
Verse 52
Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa Re, Atobi