Back to Languages

    Yoruba - Chapter 73

    Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

    Verse 1

    Iwo oludasobora

    Verse 2

    Dide (kirun) ni oru ayafi fun igba die

    Verse 3

    Lo ilaji re tabi din die ku ninu re

    Verse 4

    Tabi fi kun un. Ki o si ke al-Ƙur’an ni pelepele

    Verse 5

    Dajudaju Awa maa gbe oro t’o lagbara fun o

    Verse 6

    Dajudaju idide kirun loru, o wonu okan julo, o si dara julo fun kike (al-Ƙur’an)

    Verse 7

    Dajudaju ise pupo wa fun o ni osan

    Verse 8

    Ranti oruko Oluwa re. Ki o si da okan ko O patapata

    Verse 9

    Oluwa ibuyo oorun ati ibuwo oorun, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, mu Un ni Alafeyinti

    Verse 10

    Ki o si se suuru lori ohun ti won n wi. Pa won ti ni ipati t’o rewa

    Verse 11

    Fi Mi da awon olupe-ododo-niro, awon oloro. Ki o si lora fun won fun igba die

    Verse 12

    Dajudaju sekeseke ati Ina Jehim n be lodo Wa

    Verse 13

    Ounje hafunhafun ati iya eleta-elero (tun wa fun won)

    Verse 14

    Ni ojo ti ile ati awon apata yoo maa mi titi pelu ohun igbe lile. Awon apata si maa di yanrin ti won kojo ti won tuka

    Verse 15

    Dajudaju Awa ran Ojise kan nise si yin (ti o je) olujerii lori yin gege bi A se ran Ojise kan nise si Fir‘aon

    Verse 16

    Sugbon Fir‘aon yapa Ojise naa. A si gba a mu ni igbamu lile

    Verse 17

    Ti eyin ba sai gbagbo, bawo ni eyin yoo se beru ojo kan t’o maa mu awon omode hewu

    Verse 18

    Sanmo si maa faya perepere ninu re. Adehun Re je ohun ti o maa se

    Verse 19

    Dajudaju eyi ni iranti. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu oju ona kan to de odo Oluwa re

    Verse 20

    Dajudaju Oluwa re mo pe dajudaju iwo n dide kirun fun ohun t’o kere si ilata meji oru tabi ilaji re tabi ilata re. Igun kan ninu awon t’o wa pelu re (naa n se bee). Allahu l’O n sodiwon oru ati osan. O si mo pe e ko le so o. Nitori naa, O ti da a pada si fifuye fun yin. Nitori naa, e ke ohun ti o ba rorun (fun yin) ninu al-Ƙur’an. O mo pe awon alaisan yoo wa ninu yin. Awon miiran si n ririn ajo lori-ile, ti won n wa ninu oore Allahu. Awon miiran si n jagun fun esin Allahu. Nitori naa, e ke ohun ti o ba rorun (fun yin) ninu re. E kirun (oran-an-yan). E yo Zakah. Ki e si ya Allahu ni dukia t’o dara. Ohunkohun ti e ba ti siwaju fun emi ara yin ninu ohun rere, eyin yoo ba a lodo Allahu ni ohun rere ati ni ohun ti o tobi julo ni esan. E toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun