Back to Languages
Yoruba - Chapter 78
Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Verse 1
Nipa ki ni won n bira won leere na
Verse 2
Nipa iro ikoko nla ni
Verse 3
eyi ti won n yapa enu si
Verse 4
Rara! Won n bo wa mo
Verse 5
Leyin naa, ni ti ododo won n bo wa mo
Verse 6
Nje Awa ko se ile ni ite bi
Verse 7
ati awon apata ni eekan (fun ile)
Verse 8
A si seda yin ni orisirisi (ako ati abo)
Verse 9
A se oorun yin ni isinmi
Verse 10
A tun se ale ni ibora
Verse 11
A tun se osan ni (asiko fun) wiwa ije-imu
Verse 12
A tun mo sanmo meje t’o lagbara soke yin
Verse 13
A tun se oorun ni imole t’o n tan gbola
Verse 14
Ati pe A so omi t’o n bo telera won kale lati inu awon esujo
Verse 15
nitori ki A le fi mu koro eso ati irugbin jade
Verse 16
pelu awon ogba t’o kun digbi fun nnkan oko
Verse 17
Dajudaju ojo ipinya, o ni gbedeke akoko kan
Verse 18
(Iyen ni) ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. Eyin yo si maa wa nijo-nijo
Verse 19
Won si maa si sanmo sile. O si maa di awon ilekun
Verse 20
Won maa mu awon apata rin (bo si aye miiran). O si maa di ahunpeena
Verse 21
Dajudaju ina Jahanamo, o lugo sile loju ona
Verse 22
(O je) ibugbe fun awon alakoyo
Verse 23
Won yoo maa gbe inu re fun igba gbooro
Verse 24
Won ko nii ri itura tabi ohun mimu kan towo ninu re
Verse 25
ayafi omi gbigbona ati awoyunweje
Verse 26
(O je) esan t’o se weku (ise won)
Verse 27
Dajudaju won ki i reti isiro-ise
Verse 28
Won si pe awon ayah Wa niro gan-an
Verse 29
Gbogbo nnkan si ni A ti se akosile re sinu Tira kan
Verse 30
Nitori naa, e to (iya) wo. A o si nii se alekun kan fun yin bi ko se iya
Verse 31
Dajudaju igbala wa fun awon oluberu (Allahu)
Verse 32
Awon ogba ati eso ajara
Verse 33
ati awon olomoge, ti won ko jura won lo lojo-ori
Verse 34
ati ife oti t’o kun denu (ni esan won)
Verse 35
Won ko nii gbo isokuso ati oro iro ninu re
Verse 36
(O je) esan lati odo Oluwa re, (o si je) ore ni ibamu si isiro-ise (won)
Verse 37
(Esan naa wa lati odo) Oluwa awon sanmo, ile ati ohun t’o wa laaarin mejeeji, Ajoke-aye. Won ko si ni ikapa oro lodo Re
Verse 38
Ojo ti molaika Jibril ati awon molaika (miiran) yoo duro ni owoowo. Won ko si nii soro afi eni ti Ajoke-aye ba yonda fun. Onitoun si maa soro t’o se weku
Verse 39
Iyen ni ojo ododo. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu ona to maa gba seri pada si odo Oluwa re pon (ni ti ironupiwada)
Verse 40
Dajudaju A fi iya t’o sunmo se ikilo fun yin. Ojo ti eniyan yoo maa wo ohun ti o ti siwaju, alaigbagbo yo si wi pe: "Yee, emi iba si je erupe, (emi iba la ninu iya)