Back to Languages
Yoruba - Chapter 85
Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Verse 1
(Allahu) bura pelu sanmo ti awon ibuso (oorun, osupa ati awon irawo) wa ninu re
Verse 2
O tun bura pelu ojo ti won se ni adehun
Verse 3
O tun bura pelu olujerii ati ohun t’o jerii si
Verse 4
A sebi le awon t’o gbe koto (ina)
Verse 5
(iyen) ina ti won n fi igi ko (ninu koto)
Verse 6
(Ranti) nigba ti won jokoo si itosi re
Verse 7
Won si n wo ohun ti won n se fun awon onigbagbo ododo
Verse 8
Ko si si kini kan ti won tori re je won niya bi ko se pe won ni igbagbo ododo ninu Allahu, Alagbara, Olope
Verse 9
Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile. Allahu si ni Elerii lori gbogbo nnkan
Verse 10
Dajudaju awon t’o fi inira kan awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, leyin naa ti won ko ronu piwada, iya ina Jahanamo n be fun won. Iya ina t’o n jo si wa fun won
Verse 11
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, tiwon ni awon Ogba Idera kan, ti awon odo n san ni isale re. Iyen si ni erenje nla
Verse 12
Dajudaju igbamu ti Oluwa re ma le
Verse 13
Dajudaju Oun ni O pile (eda), O si maa da (eda) pada (fun ajinde)
Verse 14
Oun ni Alaforijin, Ololufe (eda)
Verse 15
Oun l’O ni Ite-ola, Eni-owo julo
Verse 16
Oluse-ohun-t’O-ba-fe
Verse 17
Sebi iro awon omo ogun ti de odo re
Verse 18
(omo ogun) Fir‘aon ati (ijo) Thamud
Verse 19
Sibesibe awon t’o sai gbagbo si n pe ododo niro
Verse 20
Allahu si yi won ka leyin won
Verse 21
Amo sa, ohun (ti A fi ranse si o ni) al-Ƙur’an alapon-onle
Verse 22
ti o wa ninu walaa ti A n so