Yoruba

Translation: yor-shaykhaburahima-la

Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

Ìlànà

Surah 1

[1] Ni oruko Allahu, Ajoke-aye, Asake-orun

[2] Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

[3] Ajoke-aye, Asake-orun

[4] Olukapa-ojo-esan

[5] Iwo nikan ni a n josin fun. Odo Re nikan si ni a n wa oore si

[6] Jijosin fun Allahu nikan soso ati diduro sinsin ninu ijosin Re itumo yii wa bee ninu surah Ali ‘Imron “Fi ese wa rinle sinu ’Islam ona taara.” Nitori naa

[7] ona awon ti O se idera fun,yato si (ona) awon eni-ibinu (iyen, awon yehudi) ati (ona) awon olusina (iyen, awon nasara)

Abaamú

Surah 2

[1] ’Alif lam mim

[2] Eyi ni Tira naa, ti ko si iyemeji ninu re. Imona ni fun awon oluberu (Allahu)

[3] awon t’o gbagbo ninu (iro) ikoko, ti won n kirun, ti won si n na ninu ohun ti A pese fun won

[4] ati awon t’o gbagbo ninu ohun ti A sokale fun o ati ohun ti A sokale siwaju re, ti won si ni amodaju nipa Ojo Ikeyin

[5] Awon wonyen wa lori imona lati odo Oluwa won. Awon wonyen, awon ni olujere

[6] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, bakan naa ni fun won, yala o kilo fun won tabi o o kilo fun won, won ko nii gbagbo

[7] Allahu fi edidi di okan won ati igboro won. Ebibo si bo iriran won. Iya nla si wa fun won

[8] O si n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “A gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin.” Won ki i si se onigbagbo ododo

[9] Won n tan Allahu ati awon t’o gbagbo ni ododo je. Won ko si le tan eni kan je bi ko se emi ara won; won ko si fura

[10] Arun kan wa ninu okan won, nitori naa Allahu se alekun arun fun won. Iya eleta-elero si wa fun won nitori pe won n paro

[11] Nigba ti won ba so fun won pe: “E ma sebaje lori ile.” Won a wi pe: “Awa ni alatun-unse.”

[12] E kiye si i! Dajudaju awon gan-an ni obileje, sugbon won ko fura

[13] Nigba ti won ba so fun won pe: “E gbagbo ni ododo gege bi awon eniyan se gbagbo.” Won a wi pe: “Se ki a gbagbo gege bi awon omugo se gbagbo ni?” E kiye si i! Dajudaju awon gan-an ni omugo, sugbon won ko mo

[14] Nigba ti won ba pade awon t’o gbagbo ni ododo, won a wi pe: “A gbagbo.” Nigba ti o ba si ku won ku awon (eni) esu won, won a wi pe: “Dajudaju awa n be pelu yin, awa kan n se yeye ni.”

[15] Allahu maa fi won se yeye. O si maa mu won lekun si i ninu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida. ti awon ise naa je ise t’o duro sori fifi oruko ise eda so oruko esan ise naa. Iru re l’o sele ninu ayah ti a n tose re lowo yii. Allahu (subhanahu wa ta'ala) ki i se oluseyeye (eni ti o maa n se yeye) tabi oniyeye (eni ti eda le fi se yeye). Eni kan ko si nii maa se yeye afi ki o je alawada oniranu. Allahu (subhanahu wa ta'ala) ki i se awada Allahu ki i se eletan. Eni kan ko nii je eletan afi ki o je opuro oluyapa-adehun. Allahu ki i se opuro. Allahu gan-an ni Ododo. Bakan naa

[16] Awon wonyen ni awon t’o fi imona ra isina. Nitori naa, okowo won ko lere, won ko si je olumona

[17] Apejuwe won da bi apejuwe eni ti o tan ina, sugbon nigba ti imole tan si ayika re tan, Allahu mu imole won lo, O si fi won sile sinu awon okunkun; won ko si riran mo

[18] Aditi, ayaya, afoju ni won; nitori naa won ko nii seri pada

[19] Tabi (apejuwe won) da bi ojo nla ti n ro lati sanmo. O mu awon okunkun, ara sisan ati monamona lowo. Won n fi ika won sinu eti won nitori igbe ara sisan fun iberu iku. Allahu si yi awon alaigbagbo ka

[20] Monamona naa fee mu iriran won lo. Nigbakigba ti o ba tan imole si won, won a rin lo ninu re. Nigba ti o ba si soookun mo won, won a duro si. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, dajudaju iba gba igboro won ati iriran won. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[21] Eyin eniyan, e josin fun Oluwa yin, Eni ti O da eyin ati awon t’o siwaju yin, nitori ki e le sora (fun iya Ina)

[22] (E josin fun) Eni ti O se ile fun yin ni ite, (O se) sanmo ni aja, O so omi ojo kale lati sanmo, O si fi mu awon eso jade ni ije-imu fun yin. Nitori naa, e ma se ba Allahu wa akegbe, e si mo (pe ko ni akegbe)

[23] Ti e ba wa ninu iyemeji nipa ohun ti A sokale fun erusin Wa, nitori naa, e mu surah kan wa bi iru re, ki e si pe awon elerii yin, yato si Allahu, ti e ba je olododo

[24] Ti e o ba si se bee, e o wule le se bee, nitori naa e sora fun Ina, eyi ti ikona re je awon eniyan ati okuta ti Won pa lese sile de awon alaigbagbo

[25] Fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere ni iro idunnu pe, dajudaju awon Ogba Idera kan n be fun won, eyi ti awon odo n san ni isale re. Nigbakigba ti A ba p’ese jije-mimu kan fun won ninu eso re, won yoo so pe: “Eyi ni won ti pese fun wa teletele.” – Won mu un wa fun won ni irisi kan naa ni (amo pelu adun otooto). – Awon iyawo mimo si n be fun won ninu Ogba Idera. Olusegbere si ni won ninu re

[26] Dajudaju Allahu ko nii tiju lati fi ohun kan bi efon tabi ohun ti o ju u lo sakawe oro. Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, won yoo mo pe dajudaju ododo ni lati odo Oluwa won. Ni ti awon t’o sai gbagbo, won yoo wi pe: “Ki ni ohun ti Allahu gba lero pelu akawe yii?” Allahu n fi si lona. O si n fi to opolopo sona. Ko si nii fi si enikeni lona ayafi awon arufin

[27] Awon t’o n ye majemu Allahu leyin ti majemu naa ti fidi mule, won tun n ja ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo, won si n se ibaje lori ile, awon wonyen gan-an ni eni ofo

[28] Bawo ni e se n sai gbagbo ninu Allahu na! Bee si ni oku ni yin (tele), O si so yin di alaaye. Leyin naa, O maa so yin di oku. Leyin naa, O maa so yin di alaaye. Leyin naa, odo Re ni won yoo da yin pada si

[29] Oun ni Eni ti O da ohunkohun t’o wa lori ile fun yin patapata. Leyin naa, O wa l’oke sanmo, O si se won togun rege si sanmo meje. Oun si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[30] iseda ile siwaju iseda sanmo gege bi ayah inu surah Baƙorah yen se fi rinle. Amo ki i se oro nipa iseda ile ni ayah surah an-Nazi‘at n soro nipa re. Allahu (subhanahu wa ta'ala) ko si lo oro t’o tumo si iseda ile ninu ayah t’O ti daruko ile iyen ayah 30 ninu surah iseda gbogbo ohun t’o maa wa ninu ile ni awon igi awon ibudo 30 (Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: “Dajudaju Emi yoo fi arole kan sori ile.” Won so pe: “Se Iwo yoo fi eni ti o maa sebaje sibe, ti o si maa teje sile? Awa si n se afomo pelu idupe fun O. A si n fi ogo fun O!" O so pe: “Dajudaju Emi mo ohun ti eyin ko mo.”

[31] Allahu fi awon oruko naa, gbogbo won patapata, mo Adam. Leyin naa, O ko won siwaju awon molaika, O si so pe: “E so awon oruko wonyi fun Mi, ti e ba je olododo.”

[32] Won so pe: “Mimo ni fun O, ko si imo kan fun wa ayafi ohun ti O fi mo wa. Dajudaju Iwo, Iwo ni Onimo, Ologbon.”

[33] O so pe: “Adam, so oruko won fun won.” Nigba ti o so oruko won fun won tan, O so pe: “Se Emi ko so fun yin pe dajudaju Emi nimo ikoko awon sanmo ati ile, Mo si nimo ohun ti e n se afihan re ati ohun ti e n fi pamo?”

[34] (Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki (Anabi) Adam.” Won si fori kanle ki i ayafi ’Iblis. O ko, o si se igberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo

[35] A si so pe: “Adam, iwo ati iyawo re, e maa gbe ninu Ogba Idera. Ki e maa je ninu re ni gbedemuke ni ibikibi ti e ba fe. Ki e si ma se sunmo igi yii, ki e ma baa wa ninu awon alabosi.”

[36] Amo Esu ye awon mejeeji lese kuro ninu Ogba Idera, o si mu won jade kuro ninu ibi ti won wa. A si so pe: "E sokale, ota ni apa kan yin je fun apa kan. Ibugbe ati nnkan igbadun si n be fun yin lori ile fun igba (die).”

[37] Leyin naa, (Anabi) Adam ri awon oro kan gba lati odo Oluwa re. O si gba ironupiwada re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[38] A so pe : “Gbogbo yin, e sokale kuro ninu re. Nigba ti imona ba de ba yin lati odo Mi, eni ti o ba tele imona Mi, ipaya ko nii si fun won. Won ko si nii banuje

[39] Awon t’o ba si sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re.”

[40] Eyin omo ’Isro’il, e ranti idera Mi, eyi ti Mo se fun yin. E mu majemu Mi se, Mo maa mu (esan) majemu yin se. Emi nikan ni ki e si paya

[41] E gbagbo ninu ohun ti Mo sokale, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu yin. E ma se je eni akoko ti o maa sai gbagbo ninu re. E ma se ta awon ayah Mi l’owo pooku.Emi nikan soso ni ki e si beru

[42] E ma da iro po mo ododo, e si ma fi ododo pamo nigba ti eyin mo (ododo)

[43] E kirun, e yo zakah, ki e si dawo te orunkun pelu awon oludawote-orunkun (lori irun)

[44] Se eyin yoo maa pa awon eniyan l’ase ohun rere, e si n gbagbe emi ara yin, eyin si n ke Tira, se e o se laakaye ni

[45] E wa oore (Allahu) pelu suuru ati irun kiki. Dajudaju o lagbara (lati se bee) ayafi fun awon olupaya (Allahu)

[46] awon t’o mo pe dajudaju awon yoo pade Oluwa won, ati pe dajudaju awon yoo pada si odo Re

[47] Eyin omo ’Isro’il, e ranti idera Mi, eyi ti Mo fi sedera fun yin. Dajudaju Emi tun soore ajulo fun yin lori awon eda (asiko yin)

[48] E beru ojo kan ti emi kan ko nii sanfaani kini kan fun emi kan. A o nii gba isipe kan lowo re.1 A o si nii gba aaro l’owo re. A o si nii ran won lowo.2 awon ayah miiran so pe isipe wa.” Won ni “Itakora niyen.” 123 ati 254 ati surah al-’Ani‘am; 6:51. Amo awon ayah t’o n so pe isipe maa wa lojo Ajinde n so nipa awon majemu ti o wa fun isipe olusipe ati olusipe-fun. Irufe awon ayah naa ni surah al-Baƙorah

[49] (E ranti) nigba ti A gba yin la lowo awon eniyan Fir‘aon, ti won n fi iya buruku je yin, ti won n dunbu awon omokunrin yin, ti won si n je ki awon obinrin yin semi. Adanwo nla wa ninu iyen fun yin lati odo Oluwa yin

[50] (E ranti) nigba ti A pin agbami odo si otooto fun yin, A si gba yin la. A te awon eniyan Fir‘aon ri. Eyin naa si n wo (won ninu agbami odo)

[51] (E ranti) nigba ti A se adehun ogoji oru fun (Anabi) Musa. Leyin naa, e tun bo oborogidi omo maalu leyin re. Alabosi si ni yin

[52] Leyin naa, A moju kuro fun yin leyin iyen nitori ki e le dupe (fun Allahu)

[53] (E ranti) nigba ti A fun (Anabi) Musa ni Tira ati oro-ipinya nitori ki e le mona

[54] (E ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: “Eyin ijo mi, dajudaju eyin sabosi si emi ara yin nipa siso oborogidi omo maalu di orisa. Nitori naa, e ronu piwada si odo Eledaa yin, ki awon ti ko bo maalu pa awon t’o bo o laaarin yin. Iyen l’oore julo fun yin ni odo Eledaa yin. O si maa gba ironupiwada yin. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[55] (E ranti) nigba ti e wi pe: “Musa, a o nii gba o gbo afi ki a ri Allahu ni ojukoroju.” Nitori naa, ohun igbe lati inu sanmo gba yin mu, e si n wo boo

[56] Leyin naa, A ji yin dide leyin iku yin, nitori ki e le dupe (fun Allahu)

[57] A tun fi esujo se iboji fun yin. A si tun so (ohun mimu) monnu ati (ohun jije) salwa kale fun yin. E je ninu awon nnkan daadaa ti A pese fun yin. Won ko si sabosi si Wa, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

[58] (E ranti) nigba ti A so pe: “E wo inu ilu yii. E je ninu ilu naa nibikibi ti e ba fe ni gbedemuke. E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba. Ki e si wi pe: “Ha ese wa danu.” A oo fori awon ese yin jin yin. A o si se alekun (esan rere) fun awon oluse-rere

[59] Awon t’o sabosi yi oro naa pada (si nnkan miiran) yato si eyi ti A so fun won. Nitori naa, A so iya kale lati sanmo le awon t’o sabosi lori nitori pe won n ru ofin

[60] (E ranti) nigba ti (Anabi) Musa toro omi fun ijo re. A si so pe: “Fi opa re na okuta.” Orisun omi mejila si san jade lati inu re. Iran kookan si ti mo ibumu won. E je, ki e si mu ninu arisiki Allahu. E ma bale je ni ti obileje

[61] (E ranti) nigba ti e wi pe: “Musa, a o nii se ifarada lori ounje eyo kan. Nitori naa, pe Oluwa re fun wa. Ki O mu jade fun wa ninu ohun ti ile n hu jade bi ewebe re, kukumba re, oka baba re, ewa re ati alubosa re.” (Anabi Musa) so pe: “Se eyin yoo fi eyi to yepere paaro eyi ti o dara julo ni? E sokale sinu ilu (miiran). Dajudaju ohun ti e n beere fun n be (nibe) fun yin.” A si mu iyepere ati osi ba won. Won si pada wale pelu ibinu lati odo Allahu. Iyen nitori pe dajudaju won n sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, won si n pa awon Anabi lai letoo. Iyen nitori pe won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu-ala

[62] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo ati awon yehudi, nasara ati awon sobi’u; enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si se ise rere, esan won n be fun won ni odo Oluwa won. Ko si iberu fun won. Won ko si nii banuje

[63] E ranti nigba ti A gba adehun yin, A si gbe apata wa soke ori yin, (A si so pe): “E gba ohun ti A fun yin mu daradara, ki e si ranti ohun t’o wa ninu re, nitori ki e le beru (Allahu)

[64] Leyin naa, e peyinda leyin iyen. Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati aanu Re lori yin, eyin iba wa ninu eni ofo

[65] Dajudaju e mo awon t’o koja enu-ala ninu yin nipa ojo Sabt. A si so fun won pe: "E di obo, eni-igbejinna si ike

[66] A si se e ni arikogbon fun eni t’o soju re ati eni t’o n bo leyin re. (O tun je) eko fun awon oluberu (Allahu)

[67] (E ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: “Dajudaju Allahu n pa yin ni ase pe ki e pa abo maalu kan.” Won wi pe: “Se o n fi wa se yeye ni!” O so pe: "Mo n sadi Allahu nibi ki ng je ara awon ope

[68] Won wi pe: “Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ewo ni.” O so pe: "Dajudaju O n so pe abo maalu ni. Ko nii je ogbologboo, ko si nii je godogbo. O maa wa laaarin (mejeeji) yen. Nitori naa, e se ohun ti Won n pa yin lase

[69] Won wi pe: “Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ki ni awo re.” O so pe: “Dajudaju O n so pe abo maalu, alawo omi-osan ni. Awo re yo si mo fonifoni, ti o maa dun-un wo l’oju awon oluworan

[70] Won wi pe: "Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ewo ni. Dajudaju awon abo maalu jora won loju wa. Ati pe dajudaju, ti Allahu ba fe, awa maa mona (ti a o gba ri i)

[71] O so pe: “Dajudaju O n so pe abo maalu ni. Ko nii je maalu yepere ti n roko. Ko si nii maa fomi won oko. O maa ni alaafia, ko si nii ni abawon kan lara.” Won wi pe: “Nisinsin yii l’o mu ododo wa.” Won si pa maalu naa. Won fee ma se e mo

[72] (E ranti) nigba ti e pa eni kan, e si n ti i sira yin. Allahu yo si safi han ohun ti e n fi pamo

[73] Nitori naa, A so pe: “E fi bure kan (lara maalu) lu (oku naa).” Bayen ni Allahu se n so oku di alaaye. O si n fi awon ami Re han yin, nitori ki e le se laakaye

[74] Leyin naa, okan yin le leyin iyen. O si da bi okuta tabi lile t’o lagbara ju bee lo. Dajudaju o n be ninu awon okuta ti awon odo n san jade lati inu re. Dajudaju o tun n be ninu won ti o maa san kankan. Omi si maa jade lati inu re. Dajudaju o tun n be ninu won ti o n wo lule gbi fun ipaya Allahu. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

[75] Nje e lero pe won yoo gba yin gbo, nigba ti o je pe igun kan ninu won kuku n gbo oro Allahu. Leyin naa, won a yi i pada sodi leyin ti won ti gbo o ye; won si mo

[76] Nigba ti won ba si pade awon t’o gbagbo ni ododo, won a wi pe: “A gbagbo.” Nigba ti o ba si ku apa kan won ku apa kan, won a wi pe: “Se ki i se pe e n ba won soro nipa ohun ti Allahu ti sipaya re fun yin, ki won le fi ja yin niyan ni odo Oluwa yin? Se e o se laakaye ni!”

[77] Se won ko mo pe dajudaju Allahu mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n safi han re

[78] Ati pe o wa ninu won, awon alaimoonkomoonka, ti won ko nimo nipa Tira afi awon oro-iro. Ki ni won (n so) bi ko se pe won n saroso

[79] Nitori naa, egbe ni fun awon t’o n fi owo ara won ko Tira, leyin naa ti won n wi pe: “Eyi wa lati odo Allahu.” Nitori ki won le ta a ni owo pooku. Egbe ni fun won se nipa ohun ti owo won ko. Egbe si ni fun won pelu nipa ohun ti won n se nise

[80] Won si wi pe: “Ina ko le fowo ba wa tayo ojo t’o lonka.” So pe: “Se e ti ri adehun kan gba lodo Allahu ni?”Allahu ko si nii yapa adehun Re. Se e fe safiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu ni

[81] Rara (Ina ko ri bi won se ro o si); enikeni ti o ba se ise ibi kan, ti awon ese re tun yi i ka, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

[82] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re

[83] (E ranti) nigba ti A gba adehun lowo awon omo ‘Isro’il pe, eyin ko gbodo josin fun olohun kan ayafi Allahu. Ki e si se daadaa si awon obi mejeeji, ibatan, awon omo orukan ati awon mekunnu. E ba awon eniyan soro rere. E kirun, ki e si yo Zakah. Leyin naa le peyin da afi die ninu yin. Eyin si n gbunri (kuro nibi adehun)

[84] (E ranti) nigba ti A gba adehun lowo yin pe eyin ko gbodo ta eje yin sile, eyin ko si gbodo lera yin jade kuro ninu ile yin. Leyin naa, e fi rinle, e si n jerii si i

[85] Leyin naa, eyin wonyi l’e n p’ara yin. E tun n le apa kan ninu yin jade kuro ninu ile won. E n fi ese ati abosi seranwo (fun awon ota) lori won. Ti won ba si wa ba yin (ti won ti di) eru, eyin n ra won (lati fi’ra yin seru). Eewo si feekan ni fun yin lati le won jade. Se eyin yoo gba apa kan Tira gbo, e si n sai gbagbo ninu apa kan? Nitori naa, ki ni esan fun eni to se yen ninu yin bi ko se abuku ninu isemi aye. Ni ojo Ajinde, won si maa da won pada sinu iya to le julo. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

[86] Awon wonyen ni awon ti won fi orun ra isemi aye. Nitori naa, A o nii gbe iya fuye fun won, A o si nii ran won lowo

[87] Dajudaju A ti fun (Anabi) Musa ni Tira. A si mu awon Ojise wa ni telentele leyin re. A tun fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fun ni agbara nipase Emi Mimo (iyen, Molaika Jibril). Se gbogbo igba ti Ojise kan ba wa ba yin pelu ohun ti okan yin ko fe ni e o maa segberaga? E si pe apa kan (awon Anabi) ni opuro, e si n pa apa kan

[88] Won si wi pe: “Ebibo bo wa lokan.” Ko si ri bee. Allahu ti sebi le won ni nitori aigbagbo won. Sebi die ni won n gbagbo

[89] Nigba ti Tira kan si de ba won lati odo Allahu, ti o n fi idi ododo mule nipa ohun ti o wa pelu won, bee si ni teletele won ti n toro isegun lori awon to sai gbagbo, amo nigba ti ohun ti won nimo nipa re de ba won, won sai gbagbo ninu re. Nitori naa, ibi dandan Allahu ki o maa ba awon alaigbagbo

[90] Aburu ni ohun ti won ra fun emi ara won nipa bi won se sai gbagbo ninu ohun ti Allahu sokale, ni ti ilara pe Allahu n so (Tira) kale ninu oore ajulo Re fun eni ti O fe ninu awon erusin Re. Won si pada pelu ibinu (miiran) lori ibinu (Allahu ti o ti wa lori won tele). Iya ti i yepere (eda) si n be fun awon alaigbagbo

[91] Nigba ti won ba so fun won pe: “E gbagbo ninu ohun ti Allahu sokale.” Won a wi pe: “A gbagbo ninu ohun ti won sokale fun wa.” Won si n sai gbagbo ninu ohun t’o wa leyin re, ti o si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu won. So pe: “Nitori ki ni e fi n pa awon Anabi Allahu teletele ti e ba je onigbagbo ododo

[92] Ati pe dajudaju (Anabi) Musa ti mu awon eri t’o yanju wa ba yin. Leyin naa, e tun bo oborogidi omo maalu leyin re. Alabosi si ni yin.”

[93] (E ranti) nigba ti A gba adehun lowo yin, A si gbe apata s’oke ori yin, (A so pe:) "E gba ohun ti A fun yin mu daradara. Ki e si teti gboro." Won wi pe: "A gbo (ase), a si yapa (ase)." Won ti ko ife bibo oborogidi omo maalu sinu okan won nipase aigbagbo won. So pe: "Aburu ni ohun ti igbagbo (iborisa) yin n pa yin lase re, ti e ba je onigbagbo ododo

[94] So pe: “Ti o ba je pe tiyin nikan ni Ile Ikeyin ti n be ni odo Allahu, ti ko si nii je ti awon eniyan (miiran), e toro iku, ti e ba je olododo

[95] Won ko nii toro iku laelae nitori ohun ti owo won ti siwaju. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi

[96] Dajudaju o maa ri won pe awon ni eniyan t’o l’oju kokoro julo nipa isemi aye, (won tun l’oju kokoro ju) awon osebo lo. Ikookan won n fe pe ti A ba le fun oun ni egberun odun lo laye. Bee si ni, ki i se ohun ti o maa la a ninu iya ni pe ki A fun un ni isemi gigun lo. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

[97] So pe: “Enikeni ti o ba je ota fun (molaika) Jibril, (o ti di ota Allahu) nitori pe dajudaju (molaika) Jibril lo mu al-Ƙur’an wa sinu okan re pelu ase Allahu. Al-Ƙur’an si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re. O je imona ati idunnu fun awon onigbagbo ododo

[98] Enikeni ti o ba je ota fun Allahu, awon molaika Re, awon Ojise Re, Jibril ati Mikal, dajudaju Allahu ni ota fun awon alaigbagbo

[99] Dajudaju A ti so awon ayah to yanju kale fun o. Eni kan ko nii sai gbagbo ninu re ayafi awon arufin

[100] Ati pe se gbogbo igba ti won ba da majemu kan ni apa kan ninu won yoo maa ju u nu? Rara, opolopo won ni ko gbagbo

[101] Ati pe nigba ti Ojise kan lati odo Allahu de ba won, ti o n jerii si eyi t’o je ododo ninu ohun t’o wa pelu won, apa kan ninu awon ti A fun ni Tira gbe Tira Allahu ju s’eyin leyin won bi eni pe won ko mo (pe asoole nipa Anabi s.a.w. wa ninu re)

[102] Won si tele ohun ti awon esu alujannu n ka (fun won ninu idan) lasiko ijoba (Anabi) Sulaemon. (Anabi) Sulaemon ko si sai gbagbo, sugbon awon esu alujannu ni won sai gbagbo, ti won n ko awon eniyan ni idan. Awa ko si so (idan) kale fun awon molaika meji naa. (Amo awon esu alujannu wonyi) Harut ati Morut ni (ilu) Babil (ni won n ko awon eniyan nidan). Won ko si nii ko enikeni ayafi ki won wi pe: "Adanwo ni wa. Nitori naa, ma di keferi." Won si n kekoo ohun ti won yoo fi sopinya laaarin omoniyan ati eni keji re lodo awon alujannu mejeeji. - Won ko si le ko inira ba enikeni ayafi pelu iyonda Allahu. - Won n kekoo ohun ti o maa ko inira ba won, ti ko si nii se won ni anfaani. Won kuku ti mo pe enikeni ti o ba ra idan, ko nii si ipin rere kan fun un ni Ojo Ikeyin. Aburu si ni ohun ti won ra fun emi ara won ti o ba je pe won mo. ti awon onimo mu wa lori re. Ma se siju wo itumo miiran … bi itan ti won ti fi esun oti mimu ati esun ipaniyan kan awon molaika… Ipile adisokan ti a ni si awon molaika yo fori sanpon nipa pipe Harut ati Morut ni molaika. Awon molaika ni eni ti Allahu ni afokantan si lori imisi Re ti O fi ran won. Awon si ni asoju Allahu fun awon Ojise Re. E wo surah at-Tahrim; 66:6 ati surah al-’Anbiya’; 21:26-27…” al-Ƙurtubiy. bi Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) se n ko awon eniyan re ni igbagbo ododo ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) fi ran an nise si won bee naa ni awon esu alujannu kan n lo ba awon eniyan lati maa ko won ni eko idan lati maa fi tako igbagbo ododo ti won n gbo lodo Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam). Nikete ti iro aburu yii deti igbo Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) l’o pase lati gba gbogbo akosile idan naa lowo won. O si bo gbogbo re mo inu ile. Amo leyin iku re

[103] Ti o ba je pe dajudaju won gbagbo ni ododo, ti won si beru (Allahu), dajudaju esan ti o maa wa lati odo Allahu l’oore julo (fun won), ti won ba mo

[104] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma so pe “ro‘ina”. (Amo) e so pe “unthurna” , ki e si maa teti gbo (oro esin). Iya eleta-elero si wa fun awon alaigbagbo

[105] Awon t’o sai gbagbo ninu awon ti A fun ni Tira ati awon osebo ko fe ki won so oore kan kan kale fun yin lati odo Oluwa yin. Allahu si n fi ike Re sa eni ti O ba fe lesa. Allahu si ni Oloore nla

[106] A o nii fi ayah kan pa ayah kan re tabi ki A fi sile (bee ni ohun kike nikan), A maa mu eyi t’o dara ju u lo tabi iru re wa. Se iwo ko mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[107] Se iwo ko mo pe dajudaju ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile? Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu

[108] Tabi e fe maa beere (orokoro) lowo Ojise yin ni gege bi won se beere (orokoro) lowo (Anabi) Musa siwaju? Enikeni ti o ba fi aigbagbo ropo igbagbo, dajudaju o ti sina (kuro) l’oju ona taara

[109] Opolopo ninu awon ti A fun ni Tira n fe lati da yin pada sipo keferi leyin ti e ti ni igbagbo ododo, ni ti keeta lati inu emi won, (ati) leyin ti ododo (’Islam) ti foju han si won. Nitori naa, e forijin won, ki e samoju kuro fun won (nipa inira ti won n fi kan yin) titi Allahu yo fi mu ase Re wa (lati ja won logun). Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[110] E kirun, e yo Zakah; ohunkohun ti e ba si ti siwaju fun emi ara yin ni rere, e maa ba a lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[111] Won wi pe: “Eni kan ko nii wo inu Ogba Idera afi eni ti o ba je yehudi tabi nasara.” Iyen ni ife-okan won. So pe: “E mu eri oro yin wa ti e ba je olododo

[112] Bee ko (won ko nii wo inu Ogba Idera afi) eni ti o ba ju ara re sile (ninu ’Islam) fun Allahu, ti o si je oluse rere. Nitori naa, esan (ise) re n be fun un lodo Oluwa re. Ko nii si iberu fun won. Won ko si nii banuje

[113] Awon yehudi wi pe: “Awon nasara ko ri nnkan kan se (ninu esin).” Awon nasara naa wi pe: “Awon yehudi ko ri nnkan kan se (ninu esin.)” Won si n ke Tira! Bayen ni awon ti ko nimo se so iru oro won (yii). Nitori naa, Allahu a dajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si

[114] Ati pe ta l’o sabosi ju eni ti o se awon mosalasi Allahu ni eewo lati seranti oruko Allahu ninu re, ti o tun sise lori iparun awon mosalasi naa? Awon wonyen, ko letoo fun won lati wo inu re ayafi pelu iberu. Abuku n be fun won n’ile aye. Ni orun, iya nla si n be fun won

[115] Ti Allahu ni ibuyo oorun ati ibuwo oorun. Nitori naa, ibikibi ti e ba doju ko ibe yen naa ni ƙiblah Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugbaaye, Onimo

[116] Won wi pe: “Allahu so eni kan di omo.” Mimo ni fun Un! Oro ko ri bee, (amo) tiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Eni kookan si ni olutele-ase Re

[117] Olupileda awon sanmo ati ile ni (Allahu). Nigba ti O ba si pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: “Je bee.” O si maa je bee

[118] Awon ti ko nimo wi pe: “Ti o ba je pe Allahu n ba wa soro ni tabi ki ami kan wa ba wa (awa iba gbagbo)?” Bayen ni awon t’o siwaju won se so iru oro won (yii). Okan won jora won. A kuku ti se alaye awon ayah fun ijo to ni amodaju

[119] Dajudaju Awa fi ododo ran o nise. (O si je) oniroo-idunnu ati olukilo (fun gbogbo aye). Won ko si nii bi o leere nipa awon ero inu Ina

[120] Awon yehudi ati nasara ko nii yonu si o titi o fi maa tele esin won. So pe: “Dajudaju imona ti Allahu ni imona.” Dajudaju ti o ba si tele ife-inu won leyin eyi ti o de ba o ninu imo (’Islam), ko nii si alaabo ati alaranse kan fun o lodo Allahu

[121] Awon ti A fun ni Tira (al-Ƙur’an), won n ke e ni kike eto. Awon wonyen gba a gbo ni ododo. Awon t’o sai gbagbo ninu re, awon wonyen ni eni ofo

[122] Eyin omo ’Isro’il, e ranti ike Mi, eyi ti Mo se fun yin. Dajudaju Emi tun soore ajulo fun yin lori awon

[123] E beru ojo kan ti emi kan ko nii sanfaani kini kan fun emi kan. A o si nii gba aaro lowo re. Isipe kan ko nii wulo fun un. A o si nii ran won lowo

[124] (E ranti) nigba ti Oluwa fi awon oro kan dan (Anabi) ’Ibrohim wo. O si pari won ni pipe. (Allahu) so pe: “Dajudaju Emi yo se o ni asiwaju fun awon eniyan.” (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Ati ninu awon aromodomo mi.” (Allahu) so pe: "Adehun Mi (lati so eni kan di Ojise) ko nii te awon alabosi lowo

[125] (E ranti) nigba ti A se Ile (Kaaba) ni aye ti awon eniyan yoo maa wa ati aye ifayabale. Ki e si mu ibuduro ’Ibrohim ni ibukirun. A si pa (Anabi) ’Ibrohim ati (Anabi) ’Ismo‘il lase pe “E se Ile Mi ni mimo fun awon oluyipo re, awon olukoraro sinu re ati awon oludawote-orunkun, awon oluforikanle (lori irun)

[126] (E ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: “Oluwa mi, se ilu yii ni ilu ifayabale. Ki O si pese awon eso fun awon ara ibe (iyen) enikeni ninu won ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin.” (Allahu) so pe: "Ati eni ti o ba sai gbagbo, Emi yoo fun un ni igbadun die. Leyin naa, Mo maa taari re sinu iya Ina. Ikangun naa si buru

[127] (E ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim ati ’Ismo‘il gbe awon ipile Ile naa duro. (Won sadua pe) "Oluwa wa, gba a lowo wa, dajudaju Iwo, Iwo ni Olugbo, Onimo

[128] Oluwa wa, se wa ni musulumi fun O. Ki O si se ninu aromodomo wa ni ijo musulumi fun O. Fi ilana esin wa han wa. Ki O si gba ironupiwada wa. Dajudaju Iwo, Iwo ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[129] Oluwa wa, gbe dide ninu won Ojise kan laaarin won, (eni ti) o maa ke awon ayah Re fun won, ti o maa ko won ni Tira ati ogbon ijinle (sunnah), ti o si maa so won di eni mimo. Dajudaju Iwo, Iwo ni Alagbara, Ologbon

[130] Ta si ni o maa ko esin (Anabi) ’Ibrohim sile afi eni ti o ba go emi ara re. A kuku ti sa a lesa n’ile aye. Dajudaju o tun wa ninu awon eni rere ni orun

[131] (E ranti) nigba ti Oluwa re so fun un pe: “Je musulumi.” O so pe: “Mo je musulumi fun Oluwa gbogbo eda.”

[132] (Anabi) ’Ibrohim si pa a lase fun awon omo re. (Anabi) Ya‘ƙub naa se bee. (Ikini keji so pe): "Eyin omo mi, dajudaju Allahu yan esin naa fun yin. Nitori naa, e o gbodo ku ayafi ki e je musulumi

[133] Tabi eyin je elerii nigba ti iku de ba (Anabi) Ya‘ƙub? Nigba ti o so fun awon omo re pe: “Ki ni eyin yoo maa josin fun leyin (iku) mi?” Won so pe: "Awa yo maa josin fun Olohun re ati Olohun awon baba re, (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il ati ’Ishaƙ, Olohun Okan soso. Awa si ni musulumi (ti a juwo juse sile) fun Un

[134] Ijo kan niyen ti o ti lo. Tiwon ni ohun ti won se nise. Tiyin ni ohun ti e se nise. Won ko si nii bi yin leere nipa ohun ti won n se nise

[135] Won wi pe: “E je yehudi tabi nasara ki e mona.” So pe: "Rara, esin (Anabi) ’Ibrohim (lesin), oluduro-deede, ko si si ninu awon osebo

[136] E so pe: “A gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa ati ohun ti Won sokale fun (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo Ya‘ƙub. (A gbagbo ninu) ohun ti Won fun (awon Anabi) Musa ati ‘Isa, ati ohun ti Won fun awon Anabi (yooku) lati odo Oluwa won. A ko ya eni kan soto ninu won. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse sile) fun Un.”

[137] Nitori naa, ti won ba gbagbo ninu iru ohun ti e gbagbo, won ti mona. Ti won ba si gbunri, won ti wa ninu iyapa (ododo). Allahu si maa to o (nibi aburu) won. Oun ni Olugbo, Onimo

[138] (E duro ti) aro Allahu. Ta si l’o dara ju Allahu lo ni aro! Awa si ni olujosin fun Un

[139] So pe: “Se eyin yo ja wa niyan nipa Allahu ni?” Oun si ni Oluwa wa ati Oluwa yin. Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Awa (musulumi) si ni olusafomo-esin fun Un

[140] Tabi e n wi pe: “Dajudaju (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo Ya‘ƙub, won je yehudi tabi nasara.” So pe: “Se eyin l’e nimo julo (nipa won ni) tabi Allahu?” Ta l’o sabosi ju eni t’o daso bo eri odo re (ti o sokale) lati odo Allahu? Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

[141] Ijo kan niyen ti o ti lo. Tiwon ni ohun ti won se nise. Tiyin ni ohun ti e se nise. Won ko si nii bi yin leere nipa ohun ti won n se nise

[142] Awon omugo ninu awon eniyan maa wi pe: “Ki ni o mu won yi kuro nibi Ƙiblah won ti won ti wa tele?” So pe: “Ti Allahu ni ibuyo oorun ati ibuwo oorun. O si n to eni ti O ba fe si ona taara (’Islam).”

[143] Bayen ni A ti se yin ni esa ijo t’o loore julo, nitori ki e le je elerii fun awon eniyan, ati nitori ki Ojise naa le je elerii fun yin. A ko si se Ƙiblah ti o wa lori re tele ni ibukoju-kirun bi ko se pe nitori ki A le se afihan eni ti o maa tele Ojise yato si eni ti o maa yise pada. Dajudaju o lagbara ayafi fun awon ti Allahu to sona. Allahu ko si nii fi igbagbo yin rare. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Onikee fun awon eniyan

[144] A kuku ri yiyi ti o n yi oju re si sanmo. Nitori naa, A o doju re ko Ƙiblah kan ti o yonu si; nitori naa, koju re si agbegbe Mosalasi Haram (ni Mokkah). Ibikibi ti e ba tun wa, e koju yin si agbegbe re. Dajudaju awon ti A fun ni Tira kuku mo pe dajudaju ododo ni (ase Ƙiblah) lati odo Oluwa won. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti won n se nise

[145] Dajudaju ti o ba fun awon ti A fun ni Tira ni gbogbo ayah, won ko nii tele Ƙiblah re. Iwo naa ko gbodo tele Ƙiblah won. Apa kan won ko si nii tele Ƙiblah apa kan. Dajudaju ti o ba tele ife-inu won leyin ohun ti o de ba o ninu imo, dajudaju nigba naa iwo wa ninu awon alabosi

[146] Awon ti A fun ni Tira, won mo Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) gege bi won se mo awon omo won. Dajudaju awon ijo kan wa ninu won ti won kuku n fi ododo pamo; won si mo

[147] Ododo naa wa lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji

[148] Ikookan (ijo elesin) l’o ni ibukojusi t’o n koju si. Nitori naa, e yara gbawaju nibi awon ise rere. Ibikibi ti e ba wa, Allahu yo mu gbogbo yin wa (ni Ojo Ajinde). Dajudaju Alagbara ni Allahu lori gbogbo nnkan

[149] Ibikibi ti o ba jade lo, koju re si agbegbe Mosalasi Haram, nitori pe dajudaju ododo ni lati odo Oluwa re. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

[150] Ibikibi ti o ba jade lo, koju re si agbegbe Mosalasi Haram. Ati pe ibikibi ti e ba wa, e koju yin si agbegbe re, nitori ki awon eniyan ma baa ni awijare lori yin, ayafi awon ti won sabosi ninu won (ti won ko ye ja yin niyan). Nitori naa, e ma se paya won. E paya Mi, nitori ki Ng le pe idera Mi fun yin ati nitori ki e le mona ooji re maa wa ni egbe otun re nikete ti oorun ba yetari. Nigba ti opin eba oke ila oorun n je ariwa-ila oorun (north-east) opin eba isale ila oorun si n je gusu-ila oorun (south-east). Nitori naa

[151] gege bi A se ran Ojise kan si yin laaarin ara yin, ti o n ke awon ayah Wa fun yin, ti o n so yin di eni mimo, ti o n ko yin ni Tira ati ogbon ijinle (sunnah), ti o si n ko yin ni ohun ti e o mo tele

[152] Nitori naa, e ranti Mi, Mo maa ranti yin. E dupe fun Mi, e ma sai moore si Mi

[153] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e fi suuru ati irun kiki toro oore (Allahu). Dajudaju Allahu n be pelu awon onisuuru

[154] E ma se pe awon ti won n pa si oju-ogun esin Allahu ni oku (iya), amo alaaye (eni ike) ni won, sugbon eyin ko fura

[155] Dajudaju A o maa dan yin wo pelu kini kan latara eru, ebi, adinku ninu awon dukia, awon emi ati awon eso. Ki o si fun awon onisuuru ni iro idunnu

[156] Awon ti (o je pe) nigba ti adanwo kan ba kan won, won a so pe: “Dajudaju Allahu l’O ni awa; dajudaju odo Re si ni awa yoo pada si.”

[157] Awon wonyen ni aforijin ati ike yo maa be fun lati odo Oluwa won. Awon wonyen, awon si ni olumona

[158] Dajudaju (apata) Sofa ati (apata) Morwah wa ninu awon arisami fun esin Allahu. Nitori naa, enikeni ti o ba se ise Hajj si Ile naa tabi o se ise ‘Umrah, ko si ese fun un lati rin yika (laaarin apata) mejeeji. Enikeni ti o ba si finnu-findo se ise asegbore, dajudaju Allahu ni Amoore, Onimo

[159] Dajudaju awon t’o n daso bo ohun ti A sokale ninu awon eri t’o yanju ati imona, leyin ti A ti se alaye re fun awon eniyan sinu Tira, awon wonyen ni Allahu n sebi le. Awon olusebi si n sebi le won

[160] Ayafi awon t’o ronu piwada, ti won se atunse, ti won si safi han ododo, nitori naa awon wonyen ni Mo maa gba ironupiwada won. Emi si ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[161] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si ku nigba ti won je alaigbagbo, awon wonyen ni egun Allahu, (egun) awon molaika ati (egun) eniyan patapata n be lori won

[162] Olusegbere ni won ninu re. Nitori naa, A o nii gbe iya fuye fun won. A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina)

[163] Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Ko si olohun kan ti ijosin to si ayafi Oun, Ajoke-aye, Asake-orun

[164] Dajudaju awon ami wa ninu iseda awon sanmo ati ile, itelentele ati iyato oru ati osan, ati awon oko oju-omi t’o n rin lori omi pelu (riru) ohun t’o n se awon eniyan ni anfaani, ati ohun ti Allahu n sokale ni omi ojo lati sanmo, ti O si n fi so ile di aye leyin ti o ti ku, ati (bi) O se fon gbogbo eranko ka si ori ile, ati iyipada ategun ati esujo ti A teba laaarin sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n se laakaye

[165] O si n be ninu awon eniyan, eni ti n josin fun awon orisa leyin Allahu. Won nifee won gege bi ife (to ye ki won ni si) Allahu. Awon t’o gbagbo ni ododo si le julo ninu ife si

[166] (Ranti) nigba ti awon ti won tele (ninu aigbagbo) maa yowo yose kuro ninu oro awon t’o tele won; (nigba ti) won ba foju ri Iya, ti ohun t’o so won po si ja patapata

[167] Awon t’o tele won yo si wi pe: “Ti o ba je pe dajudaju ipadawaye le wa fun wa ni, awa iba yowo yose kuro ninu oro won ni gege bi won se yowo yose kuro ninu oro wa.” Bayen ni Allahu yo se fi awon ise won han won ni (ise) ofo fun won. Won ko si nii jade kuro ninu Ina

[168] Eyin eniyan, e je ninu ohun ti n be ninu ile (t’o je) eto (ati nnkan) daadaa.E ma si se tele awon oju-ese Esu. Dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

[169] Ohun ti o maa pa yin ni ase re ni (ise) aburu, ibaje ati siso nipa Allahu ohun ti e o nimo re

[170] Nigba ti won ba so fun won pe

[171] Apejuwe awon to sai gbagbo da bi apejuwe eni ti o n ke pe ohun ti ko le gboro tayo ipe ati igbe (asan). Aditi, ayaya, afoju ni won; won ko si nii se laakaye

[172] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je ninu awon nnkan daadaa ti A pese fun yin, ki e si dupe fun Allahu ti o ba je pe Oun nikan soso ni e n josin fun

[173] Ohun ti (Allahu) se ni eewo fun yin ni okunbete, eje, eran elede ati ohun ti won pe oruko miiran le lori yato si (oruko) Allahu. Sugbon eni ti won ba fi inira (ebi) kan, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, ko si ese fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[174] Dajudaju awon t’o n daso bo ohun ti Allahu sokale ninu Tira, ti won si n ta a ni owo pooku, awon wonyen ko je kini kan sinu won bi ko se Ina. Allahu ko si nii ba won soro ni Ojo Ajinde, ko si nii fo won mo (ninu ese). Iya eleta-elero si wa fun won

[175] Awon wonyen ni awon t’o fi imona ra isina, (won tun fi) aforijin ra iya. Bawo ni won se maa le sefarada fun Ina na

[176] Iyen ri bee nitori pe dajudaju Allahu so Tira (al-Ƙur’an) kale pelu ododo. Dajudaju awon t’o si yapa Tira naa ti wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo)

[177] Ki i se ohun rere ni ki e koju si agbegbe ibuyo oorun ati ibuwo oorun, amo (oluse) rere ni enikeni t’o ba gbagbo ninu Allahu, Ojo Ikeyin, awon molaika, Tira (al-Ƙur’an), ati awon Anabi. Tohun ti ife ti oluse-rere ni si owo, o tun n fi owo naa tore fun awon ebi, awon omo orukan, awon mekunnu, onirin-ajo (ti agara da), awon atoroje ati (itusile) l’oko eru. (Eni rere) yo maa kirun, yo si maa yo Zakah. (Eni rere ni) awon t’o n mu adehun won se nigba ti won ba se adehun ati awon onisuuru nigba airina-airilo, nigba ailera ati l’oju ogun esin. Awon wonyen ni awon t’o se (ise) ododo. Awon wonyen, awon si ni oluberu (Allahu)

[178] Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se esan gbigba nibi ipaniyan ni oran- anyan fun yin. Olominira fun olominira, eru fun eru, obinrin fun obinrin. Enikeni ti won ba samoju kuro kini kan fun lati odo omo iya (eni ti won pa, ki eni ti o maa gba owo emi dipo emi) se ohun rere tele (owo ti o gba, ki eni ti o maa san’wo emi) san owo naa fun un ni ona t’o dara. Iyen ni igbefuye ati aanu lati odo Oluwa yin. Sugbon enikeni ti o ba tayo enu-ala (ofin) leyin iyen, iya eleta-elero n be fun un

[179] Isemi wa fun yin ninu (ofin) igbesan ipaniyan, eyin onilaakaye, ki e le beru (Allahu)

[180] A se e ni oran-anyan fun yin, nigba ti iku ba de ba eni kan ninu yin, ti o si fi dukia sile, pe ki o so asoole ni ona t’o dara fun awon obi mejeeji ati awon ebi. (Eyi je) ojuse fun awon oluberu (Allahu)

[181] Enikeni ti o ba yi i pada leyin ti o ti gbo o, ese re yo si wa lorun awon t’o n yi i pada. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

[182] Sugbon eni ti o ba beru asise tabi iwa ese lati odo eni ti o so asoole, ti o si se atunse laaarin (awon ti ogun to si). Nitori naa, ko si ese fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[183] Eyin ti e gbagbo ni ododo, A se aawe naa ni oran-anyan fun yin, gege bi A ti se e ni oran-anyan fun awon t’o siwaju yin, nitori ki e le beru (Allahu)

[184] (E gba aawe naa) fun awon ojo ti o ni onka. (Sugbon) enikeni ninu yin ti o ba je alaisan, tabi o wa lori irin-ajo, (o maa san) onka (gbese aawe re) ni awon ojo miiran. Ati pe itanran (iyen) fifun mekunnu ni ounje l’o di dandan fun awon t’o maa fi inira gba aawe. Enikeni ti o ba finnufindo se (alekun) ise oloore, o kuku loore julo fun un. Ati pe ki e gba aawe loore julo fun yin ti e ba mo

[185] Osu Romodon eyi ti A so al-Ƙur’an kale ninu re 1 (ti o je) imona, awon alaye ponnbele nipa imona ati oro-ipinya 2 fun awon eniyan; nitori naa, enikeni ti o ba wa ninu ilu re ninu yin ninu osu naa, 3 ki o gba aawe osu naa. Enikeni ti o ba je alaisan tabi ti o ba wa lori irin-ajo, (o maa san) onka (gbese aawe re) ni awon ojo miiran. Allahu fe irorun fun yin, ko si fe inira fun yin. E pe onka (ojo aawe), ki e si gbe titobi fun Allahu nitori pe O fi ona mo yin ati nitori ki e le dupe fun Un. aye kan naa ni oke ‘Arafah wa sugbon ko pon dandan ki gbogbo aye bere aawe Romodon ni ojo kan naa ti a ba fe ki ojo ibere aawe Romodon wa ati ipari re maa je ojo kan naa gege bi o se pon dandan bee ninu ofin ’Islam a bukata si nnkan meji gbooro. Ikini: asiwaju eyo kan soso ti o maa je onisunnah

[186] Nigba ti awon erusin Mi ba bi o leere nipa Mi, dajudaju Emi ni Olusunmo. Emi yoo jepe adua aladuua nigba ti o ba pe Mi. Ki won je’pe Mi (nipa itele ase Mi). Ki won si gba Mi gbo nitori ki won le mona (gbigba adua)

[187] Won se ale aawe ni eto fun yin lati sunmo awon iyawo yin; awon ni aso yin, eyin si ni aso won. Allahu mo pe dajudaju e n tan ara yin je (nipa aife sun oorun ife ni ale aawe). O ti gba ironupiwada yin, O si se amojukuro fun yin. Ni bayii, e sunmo won, ki e si wa ohun ti Allahu ko mo yin (ni omo). E je, e mu titi e o fi ri iyato laaarin owu funfun (iyen, imole owuro) ati owu dudu (iyen, okunkun oru) ni afemojumo. Leyin naa, e pari aawe naa si ale (nigba ti oorun ba wo). E ma se sunmo won nigba ti e ba n kora ro ninu awon mosalasi. Iwonyen ni awon enu-ala (ti) Allahu (gbekale), e ma se sunmo on. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun awon eniyan nitori ki won le beru (Re)

[188] Eyin ko gbodo fi eru je dukia yin laaarin ara yin. Eyin ko si gbodo gbe dukia lo ba awon adajo (ni abetele) nitori ki e le fi ese je ipin kan ninu dukia awon eniyan, eyin si mo

[189] Won n bi o leere nipa iletesu. So pe: “Ohun ni (onka) akoko fun awon eniyan ati (onka akoko fun) ise Hajj. Ki i se ise rere (fun yin) lati gba eyin-inkule wonu ile, sugbon (oluse) rere ni eni ti o ba beru (Allahu). E gba enu-ona wonu ile. Ki e si beru Allahu nitori ki e le jere

[190] Fun aabo esin Allahu, e pa awon t’o n ja yin logun. Ki e si ma se tayo enu-ala. Dajudaju Allahu ko nifee awon olutayo enu-ala

[191] E pa won nibikibi ti owo yin ba ti ba won. Ki e si le won jade kuro nibi ti won ti le yin jade. Ifooro le ju pipa lo. E ma se ba won ja ni Mosalasi Haram afi igba ti won ba ba yin ja ninu re. Nitori naa, ti won ba ba yin ja, e ba won ja. Bayen ni esan awon alaigbagbo

[192] Ti won ba si jawo (ninu iborisa), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[193] E gbogun ti won titi ko fi nii si ifooro (iborisa) mo. Esin ’Islam yo si wa (ni ominira) fun Allahu. Nitori naa, ti won ba jawo (ninu iborisa), ko si ogun mo ayafi lori awon alabosi

[194] Osu owo fun osu owo. Awon nnkan owo si ni (ofin) igbesan. Nitori naa, enikeni ti o ba tayo enu-ala si yin, e gb’esan itayo enu-ala lara re pelu iru ohun ti o fi tayo enu-ala si yin. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu n be pelu awon oluberu (Re)

[195] E nawo fun ogun esin Allahu. Ki e si ma se fi owo ara yin fa iparun (nipa sisa fun ogun esin). E se rere. Dajudaju Allahu nifee awon oluse-rere

[196] E se asepe ise Hajj ati ‘Umrah fun Allahu. Ti won ba si se yin mo oju ona, e fi eyi ti o ba rorun ninu eran se ore. Eyin ko si gbodo fa irun ori yin titi di igba ti eran ore naa yo fi de aye re. Enikeni ninu yin ti o ba je alaisan tabi inira kan n be ni ori re, o maa fi aawe tabi saraa tabi eran pipa se itanran (fun kikanju fa irun ori). Nigba ti e ba fokanbale (ninu ewu), enikeni ti o ba se ‘Umrah ati Hajj ninu osu ise Hajj, o maa fi eyi ti o ba rorun ninu eran se ore. Eni ti ko ba ri (eran ore), ki o gba aawe ojo meta ninu (ise) hajj, meje nigba ti e ba dari wale. Iyen ni (aawe) mewaa t’o pe. Iyen wa fun eni ti ko si ebi re ni Mosalasi Haram. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu le (nibi) iya

[197] Hajj sise (wa) ninu awon osu ti A ti mo. Nitori naa, enikeni ti o ba se e ni oran-anyan lori ara re lati se Hajj ninu awon osu naa, ko gbodo si oorun ife, ese dida ati ariyanjiyan ninu ise Hajj. Ohunkohun ti e ba se ni rere, Allahu mo on. E mu ese irin-ajo lowo. Dajudaju ese irin-ajo t’o loore julo ni isora (nibi ese elomiiran ati agbe sise l’asiko ise Hajj). E beru Mi, eyin onilaakaye

[198] Ko si ibawi fun yin (nibi owo sise l’asiko ise hajj) pe ki e wa oore kan lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ti e ba n dari bo lati ‘Arafah, e se iranti Allahu ni aye alapon-onle (Muzdalifah). E se iranti Re gege bi O se fi ona mo yin, bi o tile je pe teletele e wa ninu awon olusina

[199] Leyin naa, e da lo si ibi ti awon eniyan ba da lo (ninu ise Hajj), ki e si toro aforijin Allahu. Dajudaju, Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[200] Nigba ti e ba pari ijosin (Hajj) yin, e seranti Allahu gege bi e se n seranti awon baba nla yin. Tabi ki iranti naa lagbara ju bee lo. Nitori naa, o n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “Oluwa wa, fun wa ni oore aye.” Ko si nii si ipin oore kan fun un ni orun

[201] O si n be ninu won, eni t’o n so pe: "Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye ati oore ni orun, ki O si so wa nibi iya Ina

[202] Awon wonyen, tiwon ni ipin oore nipa ohun ti won se nise. Allahu si ni Oluyara nibi isiro-ise

[203] E seranti Allahu laaarin awon ojo t’o ni onka. Nitori naa, eni ti o ba kanju (se e) fun ojo meji, ko si ese fun un. Eni ti o ba keyin (ti o duro di ojo keta), ko si ese fun un fun eni ti o ba sora (fun iwa ese). E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju won yoo ko yin jo si odo Re

[204] O n be ninu awon eniyan, eni ti oro (enu) re yo maa se o ni kayefi ninu isemi aye yii, ti yo si maa fi Allahu jerii si ohun ti n be ninu okan re (pe ko si ija), onija t’o le julo si ni

[205] Nigba ti o ba si yise pada, o maa sise kiri lori ile nitori ki o le sebaje sori ile, ki o si le pa nnkan oko ati eran-osin run. Allahu ko si feran ibaje

[206] Ati pe nigba ti won ba so fun un pe: “Beru Allahu.” Igberaga si maa mu un dese. Nitori naa, ina Jahanamo yoo to o (ni esan). Ibugbe naa si buru

[207] O n be ninu awon eniyan, eni t’o n ta emi ara re lati wa iyonu Allahu. Allahu si ni Alaaanu fun awon erusin (Re)

[208] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ko s’inu esin ’Islam patapata. Eyin ko si gbodo tele oju-ese Esu. Dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

[209] Nitori naa, ti ese yin ba ye (kuro ninu ’Islam) leyin ti awon eri t’o yanju ti de ba yin, ki e mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

[210] Se won n reti kini kan bi ko se pe ki Allahu wa ba won ninu iboji esujo, awon molaika naa (si maa wa, nigba naa) A o si yanju oro (isiro ise eda)! Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

[211] Bi awon omo ’Isro’il leere pe: “Meloo ni A ti fun won ninu ayah t’o yanju?” Enikeni ti o ba (fi aigbagbo) jiro idera Allahu leyin ti o de ba a, dajudaju Allahu le (nibi) iya

[212] Won se isemi aye ni oso (etan) fun awon alaigbagbo. (Ti aye ba si ye won tan,) won yo maa fi awon t’o gbagbo ni ododo se yeye. Awon t’o si beru Allahu maa wa l’oke won ni Ojo Ajinde. Ati pe Allahu n pese arisiki fun eni ti O ba fe lai la isiro lo

[213] Awon eniyan je ijo kan soso (elesin ’Islam nipile). Allahu si gbe awon Anabi dide ni oniroo idunnu ati olukilo. O so Tira kale fun won pelu ododo nitori ki O le fi se idajo laaarin awon eniyan nipa ohun ti won yapa enu si. Ko si si eni t’o yapa enu (si ’Islam) afi awon ti A fun ni Tira, leyin ti awon eri t’o yanju de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Nitori naa, Allahu to awon t’o gbagbo ni ododo sona pelu iyonda Re nipa ohun ti awon olote1 yapa enu si nipa ododo (’Islam). Allahu yo maa to eni ti O ba fe si ona taara

[214] Tabi e lero pe e maa wo inu Ogba Idera nigba ti irufe (adanwo) t’o kan awon t’o ti lo siwaju yin ko ti i kan yin? Iponju ati ailera mu won. Won si ri amiwo to bee ge ti Ojise ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re fi so pe: “Igba wo ni aranse Allahu maa de se?” Kiye si i! Dajudaju aranse Allahu sunmo

[215] Won n bi o leere pe ki ni awon yo maa nawo si. So pe: "Ohun ti e ba na ninu ohun rere, ki o maa je ti awon obi mejeeji, awon ebi, awon omo orukan, awon mekunnu ati onirin-ajo (ti agara da). Ohunkohun ti e ba se ninu ohun rere, dajudaju Allahu ni Onimo nipa re

[216] A se ogun esin ni oran-anyan le yin lori, ohun ikorira si ni fun yin. O si le je pe e korira kini kan, ki ohun naa si je oore fun yin. O si tun le je pe e nifee si kini kan, ki ohun naa si je aburu fun yin. Allahu nimo, eyin ko si nimo

[217] Won n bi o leere nipa ogun jija ninu osu owo. So pe: "Ese nla ni ogun jija ninu re. Ati pe siseri awon eniyan kuro l’oju ona (esin) Allahu, sise aigbagbo ninu Allahu, didi awon musulumi lowo lati wo inu Mosalasi Haram ati lile awon musulumi jade kuro ninu re, (iwonyi) tun tobi julo ni ese ni odo Allahu." Ifooro si buru ju ipaniyan lo. Won ko ni yee gbogun ti yin titi won yo fi se yin lori kuro ninu esin yin, ti won ba lagbara (ona lati se bee). Enikeni ninu yin ti o ba seri kuroninu esin re, ti o si ku si ipo keferi, nitori naa awon wonyen ni awon ise won ti baje ni aye ati ni orun. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

[218] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, awon t’o gbe ilu (won) ju sile ati awon t’o jagun fun esin Allahu, awon wonyen n reti ike Allahu. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[219] Won n bi o leere nipa oti ati tete. So pe: "Ese nla ati awon anfaani kan wa ninu mejeeji fun awon eniyan. Ese mejeeji si tobi ju anfaani won lo." Won tun n bi o leere pe ki ni awon yo maa na ni saraa. So pe: “Ohun ti o ba seku leyin ti e ba ti gbo bukata inu ile tan (ni ki e fi se saraa).” Bayen ni Allahu se n s’alaye awon ayah fun yin nitori ki e le ronu jinle

[220] nipa aye ati orun. Won n bi o leere nipa awon omo orukan. So pe: "Sise atunse dukia won (lai nii da a po mo dukia yin) l’o dara julo. Ti e ba si da a po mo dukia yin, omo iya yin (ninu esin) kuku ni won. Allahu si mo obileje yato si alatun-unse. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe (ki e ya dukia won si oto nikan ni) iba ko inira ba yin. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

[221] E ma fi awon aborisa lobinrin saya titi won yo fi gbagbo ni ododo. Dajudaju erubinrin onigbagbo ododo loore ju aborisa lobinrin, koda ki aborisa lobinrin jo yin loju. E ma si fi onigbagbo ododo lobinrin fun awon aborisa lokunrin titi won yo fi gbagbo ni ododo. Erukunrin onigbagbo ododo loore ju aborisa lokunrin, koda ki aborisa lokunrin jo yin loju. Awon (aborisa) wonyen n pepe sinu Ina. Allahu si n pepe sinu Ogba Idera ati aforijin pelu iyonda Re. O si n salaye awon ayah Re fun awon eniyan nitori ki won le lo iranti

[222] Won si n bi o leere nipa nnkan osu (obinrin). So pe: “Inira ni (sisunmo won lasiko naa). Nitori naa, e yera fun awon obinrin l’asiko nnkan osu. E ma se sunmo won (fun oorun ife) titi won yo fi se imora. Ti won ba si ti se imora, e sunmo won ni aye ti Allahu pa lase fun yin. Dajudaju Allahu nifee awon oluronu-piwada. O si nifee awon olumora

[223] Awon obinrin yin, oko ni won fun yin. E lo s’inu oko yin bi e ba se fe, ki e si ti (ise rere) siwaju fun emi ara yin. E beru Allahu. Ki e mo pe dajudaju e maa pade Re. Ki o si fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu

[224] E ma se fi Allahu se ikewo fun ibura yin pe e o nii se rere, e o nii sora (nibi iwa ese), e o si nii se atunse laaarin awon eniyan. Allahu ni Olugbo, Onimo

[225] Allahu ko nii fi ibura yin ti ko ti inu yin wa bi yin, sugbon O maa fi ohun ti o ba t’inu okan yin wa bi yin. Allahu ni Alaforijin, Alafarada

[226] Ikoraro fun osu merin wa fun awon t’o bura pe awon ko nii sunmo obinrin won. Ti won ba seri pada (laaarin igba naa), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[227] Ti won ba si pinnu ikosile, (ki won ko won sile.) Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

[228] Awon obinrin ti won ko sile maa kora ro fun nnkan osu meta. Ko si letoo fun won lati fi ohun ti Allahu s’eda (re) s’inu apo-omo won pamo, ti won ba je eni to gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Awon oko won ni eto si dida won pada l’aaarin (asiko) yen, ti won ba gbero atunse. Awon iyawo ni eto l’odo oko won gege bi iru eyi ti awon oko won ni l’odo won lona t’o dara. Ipo ajulo tun wa fun awon okunrin lori won. Allahu ni Alagbara, Ologbon

[229] Ee meji ni ikosile. Nitori naa, e mu won mora pelu daadaa tabi ki e fi won sile pelu daadaa. Ko si letoo fun yin lati gba kini kan ninu ohun ti e ti fun won ayafi ti awon mejeeji ba n paya pe awon ko nii le so awon enu-ala (ofin) Allahu (laaarin ara won). Nitori naa, ti e ba n paya pe awon mejeeji ko nii le so awon enu-ala (ofin) Allahu, ko si ese fun won nigba naa nipa ohun ti obinrin ba fi serapada (emi ara re) Iwonyi ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale. Nitori naa, e ma se tayo re. Enikeni ti o ba tayo awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale, awon wonyen ni alabosi

[230] Nitori naa, ti oko ba ko o (ni ee keta), obinrin naa ko letoo si i mo leyin naa titi obinrin naa yo fi fe elomiiran. Ti eni naa ba tun ko o sile, ko si ese fun awon mejeeji nigba naa lati pada si odo ara won, ti awon mejeeji ba ti lero pe awon maa so awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbekale. Iwonyen ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbekale (fun won), ti O n salaye re fun ijo t’o nimo

[231] Nigba ti e ba ko awon obinrin sile (ni ee kini tabi ee keji), ti asiko (opo) won sunmo ko pari, e le mu won mora pelu daadaa tabi ki e tu won sile (ni ipari opo won) pelu daadaa. E ma se mu won mora ni ona inira lati le tayo enu-ala. Enikeni ti o ba se iyen, o kuku ti sabosi si emi ara re. E ma se so awon ayah Allahu di nnkan yeye. E ranti idera Allahu lori yin ati ohun ti O sokale fun yin ninu Tira ati oye ijinle (iyen, sunnah Anabi s.a.w.), ti O n fi se isiti fun yin. E beru Allahu, ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[232] Nigba ti e ba ko awon obinrin sile (ni ee kini tabi ee keji), ti won si pari asiko (opo) won, e ma se di won lowo lati fe oko won, nigba ti won ba jo yonu sira won (ti won si gba) ona to dara . Iyen ni A n fi se waasi fun enikeni ninu yin, t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Iyen l’o fo yin mo julo. O si tun safomo (okan yin) julo. Allahu nimo, eyin ko si nimo

[233] Awon abiyamo yoo maa fun awon omo won ni oyan mu fun odun meji gbako, fun eni ti o ba fe pari (asiko) ifomoloyan. Ojuse ni fun eni ti won bimo fun lati maa se (eto) ije-imu won ati aso won ni ona t’o dara. Won ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. Won ko nii ko inira ba abiyamo nitori omo re. Won ko si nii ko inira ba eni ti won bimo fun nitori omo re. Iru (ojuse) yen tun n be fun olujogun. Ti awon mejeeji ba si fe gba oyan l’enu omo pelu ipanupo ati asaro awon mejeeji, ko si ese fun awon mejeeji. Ti e ba si fe gba eni ti o maa fun awon omo yin loyan mu, ko si ese fun yin, ti e ba ti fun won ni ohun ti e fe fun won (ni owo-oya) ni ona t’o dara. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[234] Awon ti oko won ku ninu yin, ti won si fi awon iyawo sile, won yoo kora ro fun osu merin ati ojo mewaa. Nigba ti won ba pari asiko (opo) won, ko si ese fun yin nipa ohun ti won ba se funra won (lati ni oko miiran) ni ona t’o dara. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[235] Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e peso ninu ibanisoro ife tabi ti e fi pamo sinu emi yin. Allahu mo pe dajudaju eyin yo maa ranti won, sugbon e ma se ba won se adehun ni ikoko, ayafi pe ki e maa so oro daadaa. E ma se pinnu ita koko yigi titi asiko (opo) maa fi pari. E mo pe dajudaju Allahu mo ohun ti n be ninu emi yin, nitori naa, e beru Re. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alafarada

[236] Ko si ese fun yin, ti e ba ko awon obinrin sile, lai ti i sunmo won tabi lai ti i so odiwon sodaaki kan fun won ni pato. Ki e si fun won ni ebun (ikosile); ki olugbooro (ninu arisiki) fi iwon (agbara) re sile, ki talika si fi iwon (agbara) re sile ni ona t’o dara. Ojuse l’o je fun awon oluse-rere

[237] Ti e ba si ko won sile siwaju ki e to sunmo won, ti e si ti so odiwon sodaaki kan fun won, ilaji ohun ti e ti sodiwon re ni sodaaki (ni ki e fun won), afi ti won ba samoju kuro (fun gbogbo re, iyen awon obinrin) tabi ti eni ti koko yigi n be ni owo re ba samoju kuro (fun gbogbo re, iyen awon oko). Ki e samoju kuro lo sunmo iberu Allahu julo. E ma se gbagbe oore ajulo aarin yin. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[238] E so awon irun (wakati maraarun) ati (ni paapaa julo) irun aarin. Ki e si duro (kirun gege bi) oluteriba fun Allahu, lai nii soro (miiran lori irun)

[239] Sugbon ti e ba n beru (ota l’oju ogun esin), e kirun yin lori irin (ese) tabi lori nnkan igun. Nigba ti okan yin ba si bale, e kirun fun Allahu gege bi O se fi ohun ti eyin ko mo (tele) mo yin

[240] Awon ti won ku ninu yin, ti won si fi awon iyawo saye lo, ki won se asoole ije-imu odun kan fun awon iyawo won, lai si nii le won jade kuro ninu ile won. Ti won ba si jade (funra won leyin ijade opo), ko si ese fun yin nipa ohun ti won ba fi’ra won se ni daadaa (lati ni oko miiran). Allahu ni Alagbara, Ologbon

[241] Nnkan igbadun ni ona t’o dara tun maa wa fun awon obinrin ti won kosile. Ojuse l’o je fun awon oluberu Allahu

[242] Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun yin, nitori ki e le se laakaye

[243] Se o o ri awon t’o jade lati inu ile won legbeegberun nitori iberu iku! Allahu si so fun won pe: “E ku.” Leyin naa, O so won di alaaye. Dajudaju Allahu ni Oloore-ajulo lori awon eniyan, sugbon opolopo eniyan ko dupe (fun Un)

[244] E jagun fun aabo esin Allahu, ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

[245] Ta ni eni ti o maa ya Allahu ni dukia t’o dara, ki Allahu si se adipele (esan) fun un ni adipele pupo? Allahu n ka oro nile, O si n te e sile. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

[246] Se o o ri awon asiwaju ninu awon omo ’Isro’il, leyin (igba Anabi) Musa? Nigba ti won wi fun Anabi tiwon pe: “Yan oba kan fun wa, ki a lo jagun fun aabo esin Allahu.” O so pe: “Sebi o se e se pe ti Won ba se ogun jija ni oran-anyan le yin lori tan e o kuku nii jagun?” Won wi pe: "Ki ni o maa di wa lowo lati jagun fun aabo esin Allahu? Won kuku ti le awa ati awon omo wa jade kuro ninu ile wa!" Amo nigba ti A se ogun esin ni oran-anyan le won lori tan, won peyin da afi die ninu won. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi

[247] Anabi won so fun won pe: “Dajudaju Allahu ti gbe Tolut dide fun yin ni oba.” Won wi pe: “Bawo ni o se le je oba le wa lori nigba ti o je pe awa ni eto si ipo oba ju u lo? Ko si ni owo pupo lowo?” O so pe: "Dajudaju Allahu sa a lesa le yin lori. O si fun un ni alekun pupo ninu imo ati okun ara. Allahu n fun eni ti O ba fe ni ijoba Re. Allahu ni Olugbaaye, Onimo

[248] Anabi won tun so fun won pe: "Dajudaju ami ijoba re ni pe, apoti yoo wa ba yin. Nnkan ifayabale lati odo Oluwa yin ati ohun t’o seku ninu ohun ti awon eniyan (Anabi) Musa ati eniyan (Anabi) Harun fi sile n be ninu apoti naa. Awon molaika maa ru u wa (ba yin). Dajudaju ami wa ninu iyen fun yin, ti e ba je onigbagbo ododo

[249] Nigba ti Tolut jade pelu awon omo ogun, o so pe: “Dajudaju Allahu maa fi odo kan dan yin wo. Nitori naa, enikeni ti o ba mu ninu re, ki i se eni mi. Eni ti ko ba to o wo dajudaju oun ni eni mi, ayafi eni ti o ba bu iwon ekunwo re kan mu.” (Sugbon) won mu ninu re afi die ninu won. Nigba ti oun ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re soda odo naa, won so pe: “Ko si agbara kan fun wa lonii ti a le fi k’oju Jalut ati awon omo ogun re.” Awon t’o mo pe dajudaju awon maa pade Allahu, won so pe: "Meloo meloo ninu awon ijo (ogun) kekere t’o ti segun ijo (ogun) pupo pelu iyonda Allahu. Allahu n be pelu awon onisuuru

[250] Nigba ti won jade si Jalut ati awon omo ogun re, won so pe: "Oluwa wa, fun wa ni omi suuru mu, fi ese wa rinle sinsin, ki O si ran wa lowo lori ijo alaigbagbo

[251] Won si segun won pelu iyonda Allahu. Dawud si pa Jalut. Allahu si fun un ni ijoba ati ogbon. O tun fi imo mo on ninu ohun ti O ba fe. Ti ko ba je pe Allahu n dena (aburu) fun awon eniyan ni, ti O n fi apa kan won dena (aburu) fun apa kan, ori ile iba ti baje. Sugbon Allahu ni Oloore ajulo lori gbogbo eda

[252] Iwonyi ni awon ayah Allahu, ti A n ke e fun o pelu ododo. Ati pe dajudaju iwo wa lara awon Ojise

[253] Awon Ojise wonyen, A soore ajulo fun apa kan won lori apa kan. O n be ninu won, eni ti Allahu ba soro (taara). O si se agbega awon ipo fun apa kan won. A fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fi Emi Mimo (iyen, molaika Jibril) ran an lowo. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, awon t’o wa leyin won iba ti bara won ja leyin ti awon eri to yanju ti de ba won. Sugbon won yapa enu (si esin ’Islam). O n be ninu won eni t’o gbagbo ni ododo (ti o je musulumi). O si n be ninu won eni t’o sai gbagbo (ti o di nasara). Ati pe ti Allahu ba fe, won iba ti ba’ra won ja, sugbon Allahu n se ohun ti O ba fe

[254] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e na ninu ohun ti A se ni arisiki fun yin siwaju ki ojo kan to de. Ko nii si tita-rira kan ninu re. Ko nii si ololufe kan, ko si nii si isipe kan (fun awon alaigbagbo). Awon alaigbagbo, awon si ni alabosi

[255] Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alaaye, Alamojuuto-eda. Oogbe ki i ta A. Ati pe oorun ki i kun Un. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ta ni eni ti o maa sipe lodo Re afi pelu iyonda Re? O mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be leyin won. Won ko si ni imo amotan nipa kini kan ninu imo Re afi ohun ti O ba fe (fi mo won). Aga Re gbaaye ju awon sanmo ati ile. Siso sanmo ati ile ko si da A lagara. Allahu ga, O tobi

[256] Ko si ijenipa ninu esin. Imona ti foju han kuro ninu isina. Enikeni ti o ba lodi si awon orisa, ti o si ni igbagbo ododo ninu Allahu, o kuku ti dimo okun t’o fokan bale julo, ti ko nii ja. Allahu ni Olugbo, Onimo

[257] Allahu ni Alaranse awon t’o gbagbo ni ododo. O n mu won jade kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Awon t’o si sai gbagbo, awon orisa ni alafeyinti won. Awon orisa n mu won jade kuro ninu imole wa sinu awon okunkun. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re

[258] Se o o ri eni t’o ba (Anabi) ’Ibrohim jiyan nipa Oluwa re, nitori pe Allahu fun un ni ijoba? Nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: “Oluwa mi ni Eni ti n so eda di alaaye. O si n so eda di oku.” O wi pe: “Emi naa n so eda di alaaye. Mo si n so eda di oku.” (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Dajudaju Allahu n mu oorun wa lati ibuyo. Mu un wa nigba naa lati ibuwo." Won si pa oro mo eni t’o sai gbagbo lenu. Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

[259] Tabi bi eni ti o koja ninu ilu kan nigba ti o ti tu torule-torule re. O so pe: “Bawo ni Allahu yo se so eyi di alaaye leyin iku re!” Allahu si so o di oku fun ogorun-un odun. Leyin naa, O gbe e dide. O so pe: “Igba wo ni o ti wa nibi?” O so pe: “Mo wa nibi fun ojo kan tabi ilaji ojo.” O so pe: “Bee ko, o wa nibi fun ogorun-un odun. Wo ounje re ati omi re, ko yi pada. Tun wo ketekete re, ki A le fi o se ami kan fun awon eniyan. Si tun wo eegun naa bi A o se to won papo mora won. Leyin naa, (wo) bi A o se da eran bo o lara. Nigba ti o foju han si i kedere (bee), o so pe: “Mo mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan.”

[260] Nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Oluwa mi, fi han mi bi Iwo yo se so awon oku di alaaye." (Allahu) so pe: “Se iwo ko gbagbo ni?” O so pe: “Rara, sugbon ki okan mi le bale ni”. (Allahu) so pe: "Mu merin ninu awon eye, ki o so won mole si odo re (ki o pa won, ki o si gun won papo mora won). Leyin naa, fi ipin ninu won sori apata kookan. Leyin naa, pe won. Won maa sare wa ba o. Ki o si mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

[261] Apejuwe awon t’o n na owo won fun esin Allahu da bi apejuwe koro eso kan ti o hu siri meje jade, ti ogorun-un koro si wa lara siri kookan. Allahu yo se adipele fun eni ti O ba fe. Allahu ni Olugbaaye, Onimo

[262] Awon t’o n na owo won fun esin Allahu, ti won ko si fi iregun ati ipalara tele ohun ti won na, esan won n be fun won lodo Oluwa won. Iberu ko nii si fun won. Won ko si nii banuje

[263] Oro rere ati aforijin loore julo si saraa ti ipalara tele. Allahu si ni Oloro, Alafarada

[264] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se fi iregun ati ipalara ba awon saraa yin je, bi eni ti n na owo re pelu sekarimi, ko si gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Apejuwe re da bi apejuwe apata kan ti erupe n be lori re. Ojo nla ro si i, o si ko erupe kuro lori re patapata. Won ko ni agbara lori kini kan ninu ohun ti won se nise. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo

[265] Apejuwe awon t’o n na owo won lati wa iyonu Allahu ati (nitori) ifeserinle ninu emi won, o da bi apejuwe ogba oko t’o wa lori ile giga kan, ti ojo nla ro si, ti awon eso re si yo jade ni ilopo meji. Ti ojo nla ko ba si ro si i, iri n se si i. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se

[266] Nje eni kan ninu yin nifee si ki oun ni ogba oko dabinu ati ajara, ti awon odo n san ni abe re, ti orisirisi eso tun wa fun un ninu re, ki ogbo de ba a, o si ni awon omo weere ti ko lagbara (ise oko sise), ki ategun lile ti ina n be ninu re kolu oko naa, ki o si jona? Bayen ni Allahu se n s’alaye awon ayah naa fun yin nitori ki e le ronu jinle

[267] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e na ninu awon nnkan daadaa ti e se nise ati ninu awon nnkan ti A mu jade fun yin lati inu ile. E ma se gbero lati na ninu eyi ti ko dara. Eyin naa ko nii gba a afi ki e diju gba a. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Oloro, Eleyin

[268] Esu n fi osi deru ba yin, o si n pa yin ni ase ibaje sise. Allahu si n se adehun aforijin ati oore ajulo lati odo Re fun yin. Allahu ni Olugbaaye, Onimo

[269] O n fun eni ti O ba fe ni oye ijinle. Eni ti A ba si fun ni oye ijinle, A kuku ti fun un ni oore pupo. Eni kan ko nii lo iranti afi awon onilaakaye

[270] Ohunkohun ti e ba na ni inawo tabi (ohunkohun) ti e ba je ni eje, dajudaju Allahu mo on. Ko si nii si oluranlowo kan fun awon alabosi

[271] Ti e ba safi han awon saraa, o kuku dara. Ti e ba si fi pamo, ti e lo fun awon alaini, o si dara julo fun yin. Allahu si maa pa awon iwa aidaa yin re fun yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[272] Imona won ko si lorun re, sugbon Allahu l’O n fi eni ti O ba fe mona. Ohunkohun ti e ba n na ni ohun rere, fun emi ara yin ni. E o si nii nawo afi lati fi wa oju rere Allahu. Ohunkohun ti e ba si na ni ohun rere, A o san yin ni esan (re) ni ekun-rere. Won ko si nii sabosi si yin

[273] (E tore) fun awon alaini ti won se (ara won monu mosalasi Anabi nitori ki won le maa jagun) fun aabo esin Allahu. Won ko si lagbara lilo-bibo lori ile (fun okowo sise). Eni ti ko mo won maa ka won kun oloro latara aisagbe. O maa mo won pelu ami won. Won ko nii toro nnkan lowo eniyan lemolemo. Ohunkohun ti e ba na ni ohun rere, dajudaju Allahu ni Onimo nipa re

[274] Awon t’o n na owo won ni oru ati ni osan, ni ikoko ati ni gbangba, esan won n be fun won ni odo Oluwa won. Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje

[275] Awon t’o n je ele ko nii dide (ninu saree) afi bi eni ti Esu fowo ba ti n ta geegee yo se dide. Iyen ri bee nitori pe won wi pe: “Owo sise da bi owo ele.” Allahu si se owo sise ni eto, O si se owo ele ni eewo. Enikeni ti waasi ba de ba lati odo Oluwa re, ti o si jawo, tire ni eyi t’o siwaju, oro re si di odo Allahu. Enikeni ti o ba si pada (sibi owo ele), awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re

[276] Allahu maa run owo ele. O si maa bu si awon ore. Allahu ko nifee gbogbo alaigbagbo, elese

[277] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won kirun, ti won si yo Zakah, esan won n be fun won ni odo Oluwa won. Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje

[278] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si fi ohun t’o seku ninu ele sile, ti e ba je onigbagbo ododo

[279] Ti e o ba se bee, e lo mo pe ogun kan lati odo Allahu ati Ojise Re (n bo wa ba yin). Ti e ba si ronu piwada, tiyin ni oju-owo yin. E o nii sabosi (si won). Won ko si nii sabosi si yin

[280] Ti (onigbese) ba je eni ti ara n ni, e wo o niran di asiko idera. Ati pe ki e fi se saraa (fun un) loore julo fun yin, ti e ba mo

[281] E beru ojo kan ti won maa da yin pada si odo Allahu. Leyin naa, Won maa san emi kookan ni esan ni ekun rere (nipa) ohun ti o se nise. Won ko si nii sabosi si won

[282] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba n se kata-kara ni awin fun gbedeke akoko kan, e se akosile re. Ki akowe se akosile re laaarin yin ni ona eto. Ki akowe ma se ko lati se akosile gege bi Allahu se fi mo on. Nitori naa. ki o se akosile. Ki eni ti eto wa lorun re pe e fun un. Ki o beru Allahu, Oluwa re. Ko ma se din kini kan ku ninu re. Ti eni ti eto wa lorun re ba je alailoye tabi alaisan, tabi ko le pe e (funra re), ki alamojuuto re ba a pe e ni ona eto. Ki e pe elerii meji ninu awon okunrin yin lati jerii si i. Ti ko ba si okunrin meji, ki e wa okunrin kan ati obinrin meji ninu awon elerii ti e yonu si; nitori pe ti okan ninu awon obinrin mejeeji ba gbagbe, okan yo si ran ikeji leti. Ki awon elerii ma se ko ti won ba pe won (lati jerii). E ma se kaaare lati se akosile re, o kere ni tabi o tobi, titi di asiko isangbese re. Iyen ni deede julo lodo Allahu. O si gbe ijerii duro julo. O tun fi sunmo julo pe eyin ko fi nii seyemeji. Afi ti o ba je kata-kara oju ese ti e n se ni atowodowo laaarin ara yin, ko si ese fun yin ti e o ba se akosile re. E wa elerii se nigba ti e ba n se kata-kara (oja awin). Won ko si nii ko inira ba akowe ati elerii. Ti e ba si se bee, dajudaju ibaje l’e se. E beru Allahu. Allahu yo si maa fi imo mo yin. Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[283] Ati pe ti e ba wa lori irin-ajo, ti eyin ko si ri akowe, e gba ohun idogo. (Sugbon) ti apa kan yin ba fi okan tan apa kan, ki eni ti won fi okan tan da ohun ti won fi okan tan an le lori pada, ki o si beru Allahu, Oluwa re. E ma se fi eri pamo. Enikeni ti o ba fi pamo, dajudaju okan re ti dese. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti e n se

[284] Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ti e ba safi han ohun t’o wa ninu emi yin, tabi e fi pamo, Allahu yo siro re fun yin (ti e ba se e nise). Leyin naa, O maa forijin eni ti O ba fe. O si maa je eni ti O ba fe niya. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[285] Ojise naa (sollalahu 'alayhi wa sallam) gbagbo ninu ohun ti won sokale fun un lati odo Oluwa re. Awon onigbagbo ododo naa (gbagbo ninu re). Eni kookan (won) gbagbo ninu Allahu, awon molaika Re, awon Tira Re ati awon Ojise Re. A ko ya eni kan soto ninu awon Ojise Re. Won si so pe: “A gbo (ase), a si tele (ase). A n toro aforijin Re, Oluwa wa. Odo Re si ni abo eda.”

[286] Allahu ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. (Esan) ohun ti o se nise (rere) n be fun un. (Iya) ohun ti o se ni’se (ibi) n be fun un pelu. Oluwa wa, ma se mu wa ti a ba gbagbera tabi (ti) a ba sasise. Oluwa wa, ma se di eru t’o wuwo le wa lori, gege bi O se di i ru awon t’o siwaju wa. Oluwa wa, ma se diru wa ohun ti ko si agbara re fun wa. Samoju kuro fun wa, forijin wa, ki O si saanu wa. Iwo ni Alafeyinti wa. Nitori naa, ran wa lowo lori ijo alaigbagbo

Ìdílé Imran

Surah 3

[1] ’Alif lam mim

[2] Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alaaye, Alamojuuto-eda

[3] O so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re. O si so Taorah ati ’Injil kale

[4] ni isaaju. Imona si ni fun awon eniyan.1 O tun so oro-ipinya (oro t’o n sepinya laaarin ododo ati iro) kale.2 Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, iya t’o le n be fun won. Allahu si ni Alagbara, Olugbesan

[5] Dajudaju Allahu, ko si kini kan t’o pamo fun Un ninu ile ati ninu sanmo

[6] Oun ni Eni ti O n yaworan yin sinu apoluke bi O se fe. Ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alagbara Ologbon

[7] Oun ni Eni ti O so Tira kale fun o; awon ayah alainipon-na wa ninu re - awon si ni ipile Tira -, onipon-na si ni iyoku. Ni ti awon ti igbunri kuro nibi ododo wa ninu okan won, won yoo maa tele eyi t’o ni pon-na ninu re lati fi wa wahala ati lati fi wa itumo (odi) fun un. Ko si si eni t’o nimo itumo re afi Allahu. Awon agba ninu imo esin, won n so pe: “A gba a gbo. Lati odo Oluwa wa ni gbogbo re (ti sokale).” Ko si eni t’o n lo iranti ayafi awon onilaakaye. ko si ayah tabi hadith kan ti o ni pon-na ti itakora won wa wo ipo “itakora toribee” (at-ta‘arudu al-haƙiƙiy). Eyi wa ni ibamu si surah an-Nisa’

[8] Oluwa wa, ma se yi wa lokan pada leyin ti O ti to wa sona. Ta wa lore ike lati odo Re, dajudaju Iwo ni Olore

[9] Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O maa ko awon eniyan jo ni ojo kan, ti ko si iyemeji ninu re. Dajudaju Allahu ki i ye adehun

[10] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan lodo Allahu. Awon wonyen, awon ni nnkan ikona

[11] (Isesi won) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won, ti won pe awon ayah Wa niro. Nitori naa, Allahu mu won nitori ese won. Allahu si le nibi iya

[12] So fun awon t’o sai gbagbo pe: "Won maa segun yin. Won si maa ko yin jo sinu ina Jahanamo. Ibugbe naa si buru

[13] Ami kuku wa fun yin nibi awon ijo meji ti won pade (ara won). Ijo kan n ja fun aabo esin Allahu. Ikeji si je alaigbagbo. Ijo keji n ri ijo kiini bi ilopo meji won ni riri oju. Allahu n fi aranse Re se ikunlowo fun eni ti O ba fe. Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun awon oluriran

[14] Won se e ni oso fun awon eniyan; ife igbadun lara awon obinrin, awon omokunrin, awon owo wura ati fadaka pupo ati awon esin ti won se ni oso, awon eran-osin ati (nnkan) oko. Iyen ni nnkan igbaye-gbadun. Odo Allahu si ni abo rere wa

[15] So pe: “Se ki ng so nnkan t’o dara ju iyen lo fun yin?” Awon t’o ba beru (Allahu), awon Ogba ti awon odo n san ni isale re n be fun won ni odo Oluwa won. Olusegbere ni won ninu re. Awon iyawo mimo ati iyonu lati odo Allahu (tun n be fun won). Allahu si ni Oluriran nipa awon erusin

[16] awon t’o n so pe: "Oluwa wa, dajudaju awa gbagbo. Nitori naa, fori awon ese wa jin wa. Ki O si so wa nibi iya Ina

[17] (Ogba Idera yen wa fun) awon onisuuru, awon olododo, awon olutele-ase Allahu, awon olunawo-fesin ati awon olutoro-aforijin ni asiko saari

[18] Allahu jerii pe dajudaju ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun. Awon molaika ati onimo esin (tun jerii bee.), Allahu ni Onideede. Ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Alagbara, Ologbon

[19] Dajudaju esin t’o wa lodo Allahu ni ’Islam. Awon ti A fun ni Tira (awon yehudi ati kristieni) ko yapa enu (si esin naa) afi leyin ti imo de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Eni t’o ba sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise

[20] Ti won ba si ja o niyan, so pe: “Emi ati eni ti o tele mi juwo juse sile fun Allahu.” Ki o si so fun awon ti A fun ni Tira ati awon alaimoonkomoonka (alainitira) pe: “Se e maa gba ’Islam?” Ti won ba gba ’Islam, won ti mona. Ti won ba si keyin (si ’Islam), ise-jije nikan ni ojuse tire. Allahu si ni Oluriran nipa awon erusin

[21] Dajudaju awon t’o n sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, ti won n pa awon Anabi lai letoo, ti won tun n pa awon eniyan ti n pase sise eto, fun won ni iro iya eleta-elero

[22] Awon wonyen ni awon ti ise won ti baje ni ile aye ati ni orun. Won ko si nii ri awon oluranlowo

[23] Se o o ri awon ti A fun ni ipin kan ninu Tira, ti A n pe sibi Tira Allahu, ki o le se idajo laaarin won, leyin naa ti ijo kan ninu won n peyin da, ti won si n gbunri

[24] Iyen nitori pe dajudaju won wi pe: “Ina ko le jo wa tayo awon ojo t’o lonka.” Ohun ti won n da ni adapa iro si tan won je ninu esin won

[25] Nitori naa, bawo ni (o se maa ri fun won) nigba ti A ba ko won jo ni ojo kan, ti ko si iyemeji ninu re? Ati pe A maa san emi kookan ni esan ohun ti o se nise ni ekun-rere. Won ko si nii sabosi si won

[26] So pe: “Allahu, Olukapa ijoba, O n fi ijoba fun eni ti O ba fe. O n gba ijoba lowo eni ti O ba fe. O n buyi kun eni ti O ba fe. O si n tabuku eni ti O ba fe. Owo Re ni oore wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[27] O n mu oru wonu osan. O n mu osan wonu oru. O n mu alaaye jade lara oku. O n mu oku jade lara alaaye. O si n se arisiki fun eni ti O ba fe ni opolopo.”

[28] Ki awon onigbagbo ododo ma se mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo (egbe won). Enikeni ti o ba se iyen, ko si kini kan fun un mo lodo Allahu. Afi (ti e ba mu won ni ore lori ahon) lati fi sora fun won ni ti wiwa aabo (fun igbagbo yin). Allahu n kilo ara Re fun yin. Odo Allahu si ni abo eda

[29] So pe: “Ti e ba fi ohun ti n be ninu okan yin pamo tabi e fi han, Allahu mo on. O si mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[30] Ni ojo ti emi kookan yoo ri ohun ti o se ninu ise rere niwaju (re) ati ohun ti o se ninu ise ibi, o maa fe ki akoko t’o jinna wa laaarin oun ati ise ibi re. Allahu si n kilo ara Re fun yin. Allahu si ni Alaaanu awon olujosin

[31] So pe: “Ti eyin ba nifee Allahu, e tele mi, Allahu maa nifee yin, O si maa fori ese yin jin yin. Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[32] So pe: “E tele (ti) Allahu ati Ojise. Ti e ba si peyin da, dajudaju Allahu ko nifee awon alaigbagbo

[33] Dajudaju Allahu sa Adam, Nuh, ara ile ’Ibrohim ati ara ile ‘Imron lesa lori awon eda (asiko tiwon)

[34] Won je aromodomo; apa kan won wa lati ara apa kan. Allahu si ni Olugbo, Onimo

[35] (E ranti) nigba ti aya ‘Imron so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi fi ohun ti n be ninu mi jejee fun O (pe) mo maa ya a soto (fun esin Re). Nitori naa, gba a lowo mi, dajudaju Iwo ni Olugbo, Onimo

[36] Nigba ti o bi i, o so pe: “Oluwa mi, dajudaju mo bi i ni obinrin - Allahu si nimo julo nipa ohun ti o bi – okunrin ko si da bi obinrin. Dajudaju emi so o ni Moryam. Ati pe dajudaju mo n fi O wa aabo fun oun ati aromodomo re lodo Esu, eni eko.”

[37] Oluwa re si gba adua naa ni gbigba daadaa. O si mu omo naa dagba ni idagba daadaa. O si fi Zakariyya se alagbato re. Igbakigba ti Zakariyya ba wole to o ninu ile ijosin, o maa ba ese (eso) lodo re. (Zakariyya a) so pe: “Moryam, bawo ni eyi se je tire?” (Moryam a) so pe: "O wa lati odo Allahu. Dajudaju Allahu n se arisiki fun eni ti O ba fe ni opolopo

[38] Ibeyen ni Zakariyya ti pe Oluwa re. O so pe: "Oluwa mi, ta mi ni ore aromodomo daadaa lati odo Re. Dajudaju Iwo ni Olugbo adua

[39] Nitori naa, awon molaika pe e nigba ti o n kirun lowo ninu ile ijosin, (won so pe): "Dajudaju Allahu n fun o ni iro idunnu nipa (bibi) Yahya. O maa fi ododo rinle nipa oro kan lati odo Allahu. (O maa je) asiwaju, ti ko si nii sunmo obinrin. (O maa je) Anabi. O si wa ninu awon eni rere

[40] (Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, bawo ni emi yoo se ni omokunrin; mo ma ti dagbalagba, agan si ni obinrin mi?” (Molaika) so pe: “Bayen ni Allahu se n se ohun ti O ba fe.”

[41] (Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, fun mi ni ami kan.” (Molaika) so pe: "Ami re ni pe iwo ko nii le ba eniyan soro fun ojo meta ayafi titoka (si nnkan). Ranti Oluwa re lopolopo. Ki o si safomo (fun Un) ni asale ati ni owuro kutu

[42] (E ranti) nigba ti awon molaika so pe: “Moryam, dajudaju Allahu sa o lesa. O fo o mo. O si sa o lesa lori awon obinrin aye (asiko tire)

[43] Moryam, tele ase Oluwa re. Fori kanle fun Un. Ki o si dawo te orunkun pelu awon oludawote-orunkun (lori irun)

[44] Iyen wa ninu iro ikoko ti A n fi imisi re ranse si o. Iwo ko kuku si lodo won nigba ti won n ju gege won (lati mo) ta ni ninu won ni o maa gba Moryam wo. Iwo ko si si lodo won nigba ti won n se ifanfa (lori re)

[45] (E ranti) nigba ti awon molaika so pe: "Moryam, dajudaju Allahu n fun o ni iro idunnu (nipa dida eda kan pelu) oro kan lati odo Re. Oruko re ni Mosih ‘Isa omo Moryam. Abiyi ni ni aye ati ni orun. O si wa lara alasun-unmo (Allahu). ninu ayah ti ali ‘Imron Allahu (subhanahu wa ta'ala) n so nipa bi awon mola’ikah se wa so asotele nipa bibi ‘Isa ('alaehi-ssolatu wa-ssalam). Awon molaika t’o wa so asotele naa ju eyo kan lo. Idi niyi ti “mola’ikah” fi je opo ninu ayah yen. Amo ninu ayah ti Moryam

[46] O maa ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba t’o ba dagba. O si wa ninu awon eni rere

[47] (Moryam) so pe: “Oluwa mi bawo ni emi yo se ni omokunrin, (nigba ti) abara kan ko fowo kan mi.” O so pe: Bayen ni Allahu se n da ohun ti O ba fe. Nigba ti O ba (gbero) lati da eda kan ohun ti O maa so fun un ni pe: "Je bee." O si maa je bee

[48] (Allahu) yoo fun un ni imo ikowe, ijinle oye, Taorah ati ’Injil

[49] (O si je) Ojise (ti A ran nise) si awon omo ’Isro’il. (O si maa so fun won pe) "Dajudaju emi ti mu ami kan wa fun yin lati odo Oluwa yin. Dajudaju emi yoo mo nnkan fun yin lati inu amo bi irisi eye. Emi yoo fe ategun sinu re. O si maa di eye pelu iyonda Allahu. Emi yoo se iwosan fun afoju ati adete, mo si maa so oku di alaaye pelu iyonda Allahu. Emi yoo maa fun yin ni iro ohun ti e n je ati ohun ti e n fi pamo sinu ile yin. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun yin, ti e ba je onigbagbo ododo

[50] Mo si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju mi ninu Taorah nitori ki emi le se ni eto fun yin apa kan eyi ti won se ni eewo fun yin. Mo ti mu ami kan wa fun yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[51] Dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara

[52] Nigba ti (Anabi) ‘Isa fura si aigbagbo lodo won (pe won fe pa oun), o so pe: “Ta ni oluranlowo mi si odo Allahu?” Awon omoleyin (re) so pe: "Awa ni oluranlowo fun (esin) Allahu. A gba Allahu gbo. Ki o si jerii pe dajudaju musulumi ni wa

[53] Oluwa wa, a gbagbo ninu ohun ti O sokale. A si tele Ojise. Nitori naa, ko wa mo awon olujerii

[54] Won dete, Allahu si dete. Allahu si l’oore julo ninu awon adete

[55] Wafat/wafah si tumo si ""ƙobd"" gbigba eni kan kuro lowo eni kan ninu surah ali ‘Imron 3:55 ati surah al-Mo’dah elesin ’Islam ni awon t’o tele ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam). Ati ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ati owo awon t’o tele e loju aye re musulumi ni won gege bi won se pera won bee ninu surah yii

[56] Ni ti awon t’o sai gbagbo, Emi yoo je won niya lile ni aye ati ni orun. Ko si nii si awon oluranlowo fun won

[57] Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, (Allahu) maa fun won ni esan won ni kikun. Allahu ko si feran awon alabosi

[58] Iyen ni A n ke fun o ninu awon ayah ati iranti ti o kun fun ogbon ijinle (iyen, al-Ƙur’an)

[59] Dajudaju iru ‘Isa lodo Allahu da bi iru Adam; (Allahu) da a lati ara erupe. Leyin naa, O so pe: “Je bee.” O si je bee. eru Olohun ati Anabi Olohun. Amo siso ti awon kristieni so Anabi ‘Isa ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) di oluwa won olugbala won

[60] Ododo ni lati odo Oluwa re. Nitori naa, ma se wa ninu awon oniyemeji

[61] Nitori naa, enikeni ti o ba ja o niyan nipa re leyin ohun ti o de ba o ninu imo, ki o so pe: “E wa! Ki a pe awon omokunrin wa ati awon omokunrin yin ati awon obinrin wa ati awon obinrin yin ati awa ati eyin naa. Leyin naa, ki a se adua taratara, ki a si toro egun Allahu le awon opuro lori.”

[62] Dajudaju eyi, ohun ni itan ododo. Ati pe ko si olohun kan ti ijosin to si afi Allahu. Dajudaju Allahu, Oun ni Alagbara, Ologbon

[63] Ti won ba si peyin da (nibi ododo naa), dajudaju Allahu ni Onimo nipa awon obileje

[64] So pe: “Eyin ahlu-l-kitab, e wa sibi oro kan t’o dogba laaarin awa ati eyin, pe a o nii josin fun eni kan afi Allahu. A o si nii fi kini kan wa akegbe fun Un. Ati pe apa kan wa ko nii so apa kan di oluwa leyin Allahu.” Ti won ba si gbunri, e so pe: “E jerii pe dajudaju musulumi ni awa.”

[65] Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e oo fi jiyan nipa (Anabi) ’Ibrohim? A ko si so at-Taorah ati al-’Injil kale bi ko se leyin re, se e ko se laakaye ni

[66] Eyin ni iwonyi ti e n jiyan nipa ohun ti e nimo nipa re! Ki ni o tun n mu yin jiyan nipa ohun ti e o nimo nipa re? Allahu nimo. Eyin ko si nimo

[67] (Anabi) ’Ibrohim ki i se yehudi, ki i se kristieni, sugbon o je oluduro-deede, musulumi. Ko si si ninu awon osebo

[68] Dajudaju awon eniyan t’o sunmo (Anabi) ’Ibrohim julo ni awon t’o tele e ati Anabi yii (Anabi Muhammad s.a.w.) ati awon t’o gbagbo ni ododo. Allahu ni Alatileyin fun awon onigbagbo ododo

[69] Igun kan ninu awon ahlul-kitab fe lati si yin lona. Won ko le si enikeni lona afi ara won, won ko si fura

[70] Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e oo fi sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, e si n jerii (si ododo re)

[71] Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e oo fi da iro po mo ododo, e si n fi ododo pamo nigba ti eyin mo (ododo)

[72] Igun kan ninu awon ahlul-kitab wi pe: “E lo gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun awon t’o gbagbo ni ododo nibere ojo, ki e si tako o nipari re, boya awon musulumi (kan) maa seri pada (seyin ninu esin ’Islam)

[73] (Won tun wi pe:) “E ma gbagbo ayafi eni ti o ba tele esin yin.” So pe: “Dajudaju imona (’Islam) ni imona ti Allahu.” (Won tun wi pe:) “(E ma gbagbo) pe won fun eni kan ni iru ohun ti Won fun yin tabi pe won yoo tako yin (ti won yo si jare yin) lodo Oluwa yin.” So pe: “Dajudaju oore ajulo wa ni owo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu ni Olugbaaye, Onimo.”

[74] (Allahu) n sa eni ti O ba fe lesa. Allahu ni Oloore nla

[75] O n be ninu awon ahlul-kitab, eni ti o je pe ti o ba fi okan tan an pelu opolopo owo, o maa da a pada fun o. O si n be ninu won, eni ti o je pe ti o ba fi okan tan an pelu owo dinar kan (owo kekere), ko nii da a pada fun o ayafi ti o ba dogo ti i lorun. Iyen nitori pe won wi pe: “Won ko le fi ona kan kan ba wa wi nitori awon alaimoonkomoonka.” Nse ni won n pa iro mo Allahu, won si mo

[76] Rara (A maa ba won wi). Enikeni ti o ba mu adehun re se, ti o si beru (Allahu), dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re)

[77] Dajudaju awon t’o n ta majemu Allahu ati ibura won ni owo kekere, awon wonyen, ko nii si ipin oore fun won ni Ojo Ikeyin. Allahu ko nii ba won soro, ko si nii siju wo won ni Ojo Ajinde. Ko si nii fo won mo (ninu ese) Iya eleta-elero si n be fun won

[78] Dajudaju ijo kan n be ninu won t’o n fi ahon won yi tira (Allahu) pada, nitori ki e le lero pe lara tira lo wa, ko si si lara tira. Won si n wi pe: “O wa lati odo Allahu.” Ko si wa lati odo Allahu. Won n paro mo Allahu, won si mo

[79] Ko letoo fun abara kan nigba ti Allahu ba fun un ni tira, ijinle oye ati ipo Anabi, leyin naa ki o maa so fun awon eniyan pe, "e je erusin fun mi leyin Allahu." Sugbon (o maa so pe) "e je olujosin fun Oluwa (ki e si maa fi eko Re ko awon eniyan) nitori pe e je eni ti n ko awon eniyan ni tira ati nitori pe e je eni ti n ko eko (nipa esin)

[80] (Anabi kan) ko si nii pa yin ni ase pe ki e so awon molaika ati awon Anabi di oluwa. Se o maa pa yin ni ase sise aigbagbo leyin ti e ti je musulumi ni

[81] (E ranti) nigba ti Allahu gba adehun lowo awon Anabi pe: “(E lo) eyi ti Mo ba fun yin ninu Tira ati ijinle oye (iyen, sunnah eni kookan won). Leyin naa, Ojise kan (iyen, Anabi Muhammad s.a.w.) yoo de ba yin; o maa fi eyi t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu yin. Nitori naa, e gbodo gba a gbo, e si gbodo ran an lowo.” (Allahu) so pe: “Nje e gba? Se e si maa lo adehun Mi yii?” Won so pe: “A gba.” (Allahu) so pe: "Nitori naa, e jerii si (adehun naa). Emi n be pelu yin ninu awon Olujerii

[82] Nitori naa, eni ti o ba keyin si (Anabi Muhammad s.a.w.) leyin (adehun) yen, awon wonyen ni obileje

[83] Se esin miiran yato si esin Allahu ni won n wa ni? Nigba ti o je pe tiRe ni gbogbo eni ti n be ninu awon sanmo ati ile juwo juse sile fun, won fe won ko. Odo Re si ni Won maa da won pada si

[84] So pe: “A gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa pelu ohun ti Won sokale fun (Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub, ati awon aromodomo (re. A gbagbo ninu) ohun ti Won fun (Anabi) Musa ati ‘Isa ati awon Anabi lati odo Oluwa won; A ko ya eni kan kan soto ninu won. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.”

[85] Enikeni ti o ba wa esin kan se yato si ’Islam, A o nii gba a lowo re. Ni Ojo Ikeyin, o si maa wa ninu awon eni ofo

[86] Bawo ni Allahu yo se fi ona mo ijo kan t’o sai gbagbo leyin igbagbo won? Won si jerii pe dajudaju Ojise naa, ododo ni. Awon eri t’o yanju si ti de ba won. Allahu ki i fi ona mo ijo alabosi

[87] Awon wonyen, esan won ni pe, dajudaju egun Allahu ati (egun) awon molaika ati (egun) gbogbo awon eniyan n be lori won

[88] Olusegbere ni won ninu egun. Nitori naa, A o nii gbe iya fuye fun won, A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina)

[89] Ayafi awon t’o ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse, nitori pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[90] Dajudaju awon t’o sai gbagbo leyin igbagbo won, leyin naa, won lekun ni aigbagbo, A o nii gba ironupiwada won. Awon wonyen ni olusina

[91] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si ku nigba ti won je alaigbagbo, A o nii gba ekun ile wura lowo enikeni ninu won, ibaa fi serapada (fun emi ara re nibi Ina). Awon wonyen ni iya eleta-elero n be fun. Ko si nii si awon oluranlowo fun won

[92] Owo yin ko le ba oore ayafi ti e ba n na ninu ohun ti e nifee si. Ati pe ohunkohun ti e ba na, dajudaju Allahu ni Onimo nipa re

[93] Gbogbo ounje lo je eto fun awon omo ’Isro’il ayafi eyi ti ’Isro’il ba se ni eewo fun emi ara re siwaju ki A to so at-Taorah kale. So pe: “Nitori naa, e mu at-Taorah wa, ki e si ka a sita ti eyin ba je olododo.”

[94] Nitori naa, enikeni ti o ba da adapa iro mo Allahu leyin iyen, awon wonyen ni alabosi

[95] So pe: "Allahu so ododo. Nitori naa, e tele esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-’Islam. Ko si si ninu awon osebo

[96] Dajudaju ile akoko ti A fi lele fun awon eniyan ni eyi ti o wa ni Bakkah . (O je ile) ibukun ati imona fun gbogbo eda

[97] Awon ami t’o yanju wa ninu re; ibuduro (Anabi) ’Ibrohim. Enikeni ti o ba wo inu re ti di eni ifayabale. Allahu se abewo si Ile naa ni dandan fun awon eniyan, t’o lagbara ona ti o maa gba debe. Enikeni ti o ba si sai gbagbo,dajudaju Allahu ni Oloro ti ko bukata si gbogbo eda

[98] So pe: "Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e oo fi sai gbagbo ninu awon ayah Allahu? Allahu si ni Arinu-rode ohun ti e n se nise

[99] So pe: "Eyin ahlul-kitab, nitori ki ni e fi n seri eni t’o gbagbo lododo kuro loju ona (esin) Allahu, e si n fe ko wo, e si jerii (si ododo ’Islam)? Allahu ki i se Onigbagbe nipa ohun ti e n se nise

[100] Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba tele apa kan ninu awon ti A fun ni tira, won maa da yin pada leyin igbagbo ododo yin si ipo alaigbagbo

[101] Bawo ni eyin se le sai gbagbo, eyin ma ni won n ke awon ayah Allahu fun, Ojise Re si wa laaarin yin! Enikeni ti o ba duro sinsin ti Allahu, A ti to o si ona taara

[102] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu bi o se to lati beru Re. Eyin ko si gbodo ku ayafi ki e wa ni ipo musulumi

[103] E duro sinsin ti okun Allahu (’Islam) ni apapo, e ma se pin si ijo otooto. Ki e si ranti ike Allahu ti n be lori yin (pe) nigba ti e je ota (ara yin nigba aimokan), O pa okan yin po mora won (pelu ’Islam), e si di omo iya pelu ike Re; ati (nigba ti) e wa leti ogbun Ina, O gba yin la kuro ninu re. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah Re fun yin nitori ki e le mona (’Islam)

[104] Ki o maa be ninu yin, ijo kan ti yoo maa pepe sibi ohun t’o loore julo, won yoo maa pase ohun rere, won yo si maa ko ohun buruku. Awon wonyen, awon si ni olujere

[105] E ma se da bi awon t’o sora won di ijo otooto, ti won si yapa enu (si ’Islam) leyin ti awon alaye t’o yanju ti de ba won. Awon wonyen si ni iya nla n be fun

[106] Ni ojo ti awon oju kan yoo funfun (imole). Awon oju kan yo si dudu. Ni ti awon ti oju won dudu, (A o bi won pe:) "Se e sai gbagbo leyin igbagbo yin ni?" Nitori naa, e to iya wo nitori pe e sai gbagbo

[107] Ni ti awon ti oju won funfun (imole), ninu ike Allahu ni won yoo wa. Olusegbere ni won ninu re

[108] Iwonyi ni awon ayah Allahu, ti A n ke e fun o pelu ododo. Allahu ko si gbero abosi kan si gbogbo eda

[109] Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

[110] E je ijo t’o loore julo, ti A gbe dide fun awon eniyan; e n pase ohun rere, e n ko ohun buruku, e si gbagbo ninu Allahu. Ti o ba je pe awon ahlul-kitab gbagbo lododo ni, iba loore julo fun won. Onigbagbo ododo wa ninu won , opolopo won si ni obileje

[111] Won ko nii ko inira ba yin ayafi ipalara die. Ti won ba si ba yin ja, won a sa fun yin. Leyin naa, A o nii ran won lowo

[112] Abuku yoo maa ba won nibikibi ti owo awon (musulumi) ba ti ba won afi (ti won ba n be) pelu aabo lati odo Allahu (iyen ni pe, ki won gba ’Islam) ati aabo lati odo awon eniyan (iyen ni pe, ki won gba lati maa san owo isakole fun ijoba ’Islam). Won seri pada pelu ibinu lati odo Allahu. Won si ko osi ba won. Iyen nitori pe, dajudaju won sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, won tun n pa awon Anabi lai letoo. Iyen nitori pe, won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu ala

[113] (Awon ahlul-kitab) ko ri bakan naa. Ijo kan t’o duro deede wa ninu awon ahlul-kitab, ti n ke awon ayah Allahu ni akoko oru, ti won si n fori kanle (lori irun)

[114] Won gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Won n pase ohun rere, won n ko ohun buruku, won si n yara nibi awon ise olooore. Awon wonyen wa ninu awon eni rere

[115] Ohunkohun ti won ba se ni ise rere, A o nii je ki won padanu esan re. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re)

[116] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, awon dukia won ati awon omo won ko nii ro won loro kini kan nibi iya lodo Allahu. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

[117] Apejuwe ohun ti won n na ninu isemi aye yii da bi apejuwe afefe ti ategun otutu lile wa ninu re. O fe lu oko awon eniyan t’o se abosi s’ori ara won. O si pa a run. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

[118] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu alafinuhan kan yato si ara yin. Won ko nii gewo aburu kuru fun yin. Won si nifee si ohun ti o maa ko inira ba yin. Ikorira kuku ti foju han lati enu won. Ohun ti o si pamo sinu okan won tobi julo. A ti salaye awon ayah fun yin, ti eyin ba je onilaakaye

[119] Kiye si i, eyin wonyi nifee won, awon ko si nifee yin. Eyin gbagbo ninu awon tira, gbogbo re (patapata). Nigba ti won ba si pade yin, won a wi pe: “Awa gbagbo.” Nigba ti o ba si ku awon nikan, won yoo maa deyin mo ika lori yin ni ti ibinu. So pe: “E ku pelu ibinu yin.” Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu awon igba-aya eda

[120] Ti daadaa kan ba kan yin, o maa ko ibanuje ba won. Ti aburu kan ba si sele si yin, won maa dunnu si i. Ti eyin ba se suuru, ti e si sora (fun won), ete won ko nii ko inira kan kan ba yin. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise

[121] (Ranti) nigba ti o ji kuro lodo awon ara ile re ni idaji kutukutu, ti o si n fi aye ibujagun han awon onigbagbo ododo, Allahu ni Olugbo, Onimo

[122] (Ranti) nigba ti ijo meji ninu yin fe sojo. Allahu si ni Alafeyinti awon mejeeji. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

[123] Allahu kuku fun yin ni isegun ni ogun Badr, nigba ti eyin je alailagbara. Nitori naa, e beru Allahu ki e le dupe (fun Un)

[124] Ranti nigba ti o n so fun awon onigbagbo ododo pe: “Se ko nii to yin ti Oluwa yin ba se iranlowo fun yin pelu egberun meta ninu awon molaika, ti Won maa sokale?”

[125] Rara (o maa to wa.). Ti eyin ba se suuru, ti e si beru Allahu, ti awon (ota) ba de ba yin lojiji, Oluwa yin yoo ran yin lowo pelu egberun maarun ninu awon molaika pelu ami idanimo lara won

[126] Allahu ko se e lasan bi ko se ki o le je iro idunnu fun yin ati nitori ki okan yin le bale pelu re. Ko si aranse lori ota (lati ibi kan kan) bi ko se lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon

[127] (Allahu se aranse naa fun yin) nitori ki O le ge apa kan danu ninu awon t’o sai gbagbo, tabi nitori ki O le doju ti won, ti won si maa pada wale lofo

[128] Ko si ohun t’o kan o ninu oro naa. Yala (Allahu) maa gba ironupiwada won tabi O maa je won niya; dajudaju alabosi ni won

[129] Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. O n forijin eni ti O ba fe, O si n je eni ti O ba fe niya. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[130] Eyin onigbagbo ododo, e ma se je ele, adipele lori adipele. Ki e si beru Allahu nitori ki e le jere

[131] Ki e si sora fun Ina ti Won ti pa lese sile de awon alaigbagbo

[132] Ki e tele ti Allahu ati Ojise nitori ki A le ke yin

[133] E yara wa aforijin lodo Oluwa yin ati Ogba Idera kan, eyi ti ibu re to awon sanmo ati ile, ti Won pa lese sile fun awon oluberu (Allahu)

[134] Awon t’o n na owo won nigba idera ati nigba inira, awon ti n gbe ibinu mi, awon alamojuukuro fun awon eniyan nibi asise; Allahu nifee awon oluse-rere

[135] Awon ti (o je pe) nigba ti won ba se ibaje kan tabi ti won ba sabosi si emi ara won, won a ranti Allahu, won a si toro aforijin fun ese won, - Ta si ni O n fori awon ese jin (eda) bi ko se Allahu. Won ko si taku sori ohun ti won se nigba ti won mo (pe ese ni)

[136] Awon wonyen, esan won lodo Oluwa won ni aforijin ati awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Esan oluse-ise rere si dara

[137] Awon oripa kan kuku ti lo siwaju yin. Nitori naa, e rin ile lo, ki e woye si bi igbeyin awon t’o pe ododo niro se ri

[138] Eyi ni alaye fun awon eniyan. Imona ati waasi si ni fun awon oluberu (Allahu)

[139] E ma se kole, e si ma se banuje; eyin l’e maa leke ti e ba je onigbagbo ododo

[140] Ti ipalara kan ba kan yin, iru ipalara bee kuku ti kan ijo keferi. Awon ojo wonyi, A n yi i po laaarin awon eniyan ni. Ati pe nitori ki Allahu le se afihan awon t’o gbagbo ni ododo ati nitori ki O le (tewo) gba awon t’o maa ku fun Un ninu yin. Allahu ko si nifee awon alabosi

[141] Ati pe (o tun ri bee) nitori ki Allahu le safomo awon t’o gbagbo ni ododo ati nitori ki O le run awon alaigbagbo

[142] Tabi e lero pe e maa wo inu Ogba Idera nigba ti Allahu ko ti i safi han awon t’o maa jagun (esin) ninu yin, ti ko si ti i safi han awon onisuuru

[143] Dajudaju e ti n fe iku (ogun esin) siwaju ki e to pade re. E kuku ti ri i (bayii), e si n woran

[144] Ki ni (Anabi) Muhammad bi ko se Ojise, ti awon Ojise kan ti lo siwaju re. Se ti o ba ku tabi ti won ba pa a, e maa peyin da (sesin)? Enikeni ti o ba peyin da (sesin) ko le ko inira kan kan ba Allahu. Allahu yo si san awon oludupe ni esan rere. awo eran okunbete ti won pa lose ki i se eewo fun lilo fun oso ile tabi oso ara. Iru awo eran okunbete ti won pa lose bee si di eto lati fi se bata beliti

[145] Ko letoo fun emi kan lati ku afi pelu iyonda Allahu. (Iku je) akosile onigbedeke. Enikeni ti o ba n fe esan (ni) aye, A maa fun un ni aye. Enikeni ti o ba si n fe esan (ni) orun, A maa fun un ni orun. A o si san awon oludupe ni esan rere

[146] Meloo meloo ninu awon Anabi ti won ti jagun esin pelu opolopo omo-eyin (won). Won ko ni irewesi okan nipa ohun ti o sele si won ni oju ogun esin Allahu. Won ko kole, won ko si jura won sile fun ota esin. Allahu si nifee awon onisuuru

[147] Ko si si ohun kan ti won so tayo pe won so pe: "Oluwa wa fori awon ese wa ati aseju wa ninu oro wa jin wa, mu ese wa duro sinsin, ki O si se aranse fun wa lori ijo alaigbagbo

[148] Nitori naa, Allahu fun won ni esan aye ati daadaa esan orun. Allahu si nifee awon oluse rere

[149] Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba tele awon t’o sai gbagbo, won maa yi yin lese pada kuro ninu esin. Nigba naa, e maa pada di eni ofo (sinu aigbagbo)

[150] Allahu si ni Alaranse yin. O si loore julo ninu awon alaranse

[151] A maa fi eru jeje sinu okan awon t’o sai gbagbo nitori pe won ba Allahu wa akegbe, eyi ti ko so eri kan kale fun. Ina si ni ibugbe won; ile awon alabosi si buru

[152] Dajudaju Allahu ti mu adehun Re se fun yin nigba ti e n pa won pelu iyonda Re, titi di igba ti e fi sojo, ti e si n jiyan si oro. E si yapa (ase Anabi) leyin ti Allahu fi ohun ti e nifee si han yin. - O wa ninu yin eni ti n fe aye, o si n be ninu yin eni ti n fe orun. - Leyin naa, (Allahu) yi oju yin kuro ni odo won, ki O le dan yin wo. O si ti samoju kuro fun yin; Allahu ni Oloore ajulo lori awon onigbagbo ododo

[153] (E ranti) nigba ti e n gunke sa lo, ti eyin ko si boju wo eni kan kan mo leyin, Ojise si n pe yin lati eyin yin. Nitori naa, (Allahu) fi ibanuje (pipa ti awon osebo pa awon kan laaarin yin) san yin ni esan ibanuje (ti e fi kan Anabi nipase aitele ase re loju ogun ’Uhd. (O ri bee) nitori ki e ma baa banuje lori ohun ti o bo fun yin ati ohun ti o sele si yin. Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[154] Leyin naa, O so ifayabale kale fun yin leyin ibanuje; oogbe ta igun kan lo ninu yin. Igun kan ti emi ara won si ti ko ironu ba, ti won si n ni erokero si Allahu lona aito, erokero igba aimokan, won si n wi pe: “Nje a ni ase kan (ti a le mu wa) lori oro naa bi!” So pe: “Dajudaju gbogbo ase n je ti Allahu.” Won n fi pamo sinu okan won ohun ti won ko le safi han re fun o. Won n wi pe: "Ti o ba je pe a ni ase kan lori oro naa ni, won iba ti pa wa sibi." So pe: “Ti o ba je pe e wa ninu ile yin, awon ti A ti ko akoole pipa si ibujagun won mo iba kuku jade lo sibe.” (Ogun yii ri bee) nitori ki Allahu le gbidanwo ohun ti n be ninu igba-aya yin ati nitori ki O le safomo ohun ti n be ninu okan yin. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda

[155] Dajudaju awon t’o peyin da ninu yin ni ojo ti ijo meji pade, dajudaju Esu l’o ye won lese nitori apa kan ohun ti won se nise. Allahu si kuku ti samoju kuro fun won. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alafarada

[156] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se da bi awon t’o sai gbagbo, ti won so fun awon omo iya won, nigba ti won n rin kiri ni ori ile tabi (nigba) ti won n jagun, pe: “Ti o ba je pe won n be ni odo wa ni, won iba ti ku, ati pe won iba ti pa won.” (Won wi bee) nitori ki Allahu le fi iyen se abamo sinu okan won. Allahu l’O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[157] Dajudaju ti won ba pa yin s’oju ogun esin Allahu tabi e ku (sinu ile), dajudaju aforijin ati aanu lati odo Allahu loore ju ohun ti e n kojo (nile aye)

[158] Dajudaju ti e ba ku (sinu ile) tabi won pa yin (s’oju ogun esin), dajudaju odo Allahu ni won maa ko yin jo si

[159] Ike kan lati odo Allahu l’o kuku ro o fun won; ti o ba je pe o je eni buruku, olokan lile, won iba ti tuka kuro lodo re. Samoju kuro fun won, ba won toro aforijin, ki o si ba won jiroro lori oro. Ti o ba si pinnu (oro kan), ki o gbarale Allahu. Dajudaju Allahu nifee awon olugbarale E

[160] Ti Allahu ba se aranse fun yin, ko si eni ti o maa bori yin. Ti O ba si yepere yin, ta si ni eni ti o maa se aranse fun yin leyin Re? Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

[161] Ko letoo fun Anabi kan lati ji mu ninu oro ogun siwaju ki won to pin in. Enikeni ti o ba ji oro ogun mu siwaju ki won to pin in, o maa da ohun ti o ji mu ninu oro ogun naa pada ni Ojo Ajinde. Leyin naa, A oo san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. A o si nii se abosi si won

[162] Se eni ti o (sise) to iyonu Allahu da bi eni ti o pada wale pelu ibinu lati odo Allahu, ibugbe re si ni ina Jahanamo? Ikangun naa si buru

[163] (Ekinni keji ero inu Ogba Idera ati ero inu Ina ni) won ni ipo (otooto) ni odo Allahu. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

[164] Allahu kuku ti se oore fun awon onigbagbo ododo nigba ti O fi le gbe Ojise kan dide si won laaarin ara won. (Ojise naa) n ke awon ayah Re fun won. O n fo won mo (ninu ese). O si n ko won ni Tira (al-Ƙur’an) ati ijinle oye (sunnah), bi o tile je pe teletele won wa ninu isina ponnbele

[165] Se gbogbo igba ti adanwo kan ba kan yin, ti e si ti fi meji iru re (kan awon keferi), ni eyin yoo maa so pe: “Ona wo ni eyi gba sele si wa?” So pe: “O wa lati odo ara yin.” Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[166] Ohun ti o sele si yin ni ojo ti iko ogun mejeeji pade (sele) pelu iyonda Allahu. Ati pe nitori ki O le safi han awon onigbagbo ododo ni

[167] (O tun ri bee) nitori ki O le safi han awon t’o sobe-selu (ninu awon musulumi). (Awon onigbagbo ododo) si so fun won pe: “E maa bo, ki a lo jagun fun esin Allahu tabi e wa daabo bo emi ara yin.” Won wi pe: “Awa iba mo ogun-un ja awa iba tele yin.” Won sunmo aigbagbo ni ojo yen ju igbagbo lo. Won n fi enu won so ohun ti ko si ninu okan won. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo

[168] Awon t’o so nipa awon omo iya won (t’o ku s’oju ogun esin) pe – ti awon si jokoo kale sile (ni tiwon), "Ti o ba je pe won tele tiwa ni, won iba ti pa won." So pe: “E yeku danu fun emi yin ti e ba je olododo.”

[169] E ma se lero pe oku (iya) ni awon ti won pa s’oju ogun esin Allahu, amo alaaye (eni ike) ni won. Won si n pese ije-imu fun won lodo Oluwa won

[170] Won n dunnu nitori ohun ti Allahu fun won ninu oore-ajulo Re. Won si n yo fun awon ti ko ti i pade won ninu awon ti won fi sile pe: “Ko si ipaya fun won. Won ko si nii banuje.”

[171] Won n ba won yo fun ike ati oore-ajulo (ti n duro de won) lodo Allahu. Ati pe dajudaju Allahu ko nii fi esan awon onigbagbo ododo rare

[172] (Awon ni) awon t’o jepe Allahu ati Ojise leyin igba ti won ti f’ara gbogbe. Esan nla wa fun awon t’o se rere, ti won si beru (Allahu) ninu won

[173] (Awon ni) awon ti awon eniyan wi fun pe: “Won ma ti kora jo de yin, nitori naa e beru won.” (Eyi) lekun igbagbo ododo won. Won si so pe: “Allahu to fun wa. O si dara ni Alamoojuto.”

[174] Nitori naa, won pada dele pelu ike ati oore-ajulo lati odo Allahu. Aburu kan ko si kan won. Ati pe won (sise) to iyonu Allahu. Allahu si ni Oloore nla

[175] Dajudaju iyen ni Esu, ti n fi awon ore re deru ba yin. Nitori naa, e ma se beru won. Ki e si beru Mi ti e ba je onigbagbo ododo

[176] Ma se je ki awon ti n sare ko sinu aigbagbo ko ibanuje ba o. Dajudaju won ko le ko inira kan ba Allahu. Allahu ko fe ki ipin kan ninu oore wa fun won ni orun (ni); iya nla si n be fun won

[177] Dajudaju awon t’o fi igbagbo ododo ra aigbagbo, won ko le ko inira kan ba Allahu. Iya eleta-elero si wa fun won

[178] Ki awon t’o sai gbagbo ma se lero pe bi A se n lora fun won je oore fun won. A kan n lora fun won nitori ki won le lekun ninu ese ni. Iya ti i yepere eda si wa fun won

[179] Allahu ko nii gbe awon onigbagbo ododo ju sile lori ohun ti e wa lori re (nibi aimo onigbagbo ododo loto yato si sobe-selu) titi O maa fi ya eni buruku soto kuro lara eni daadaa. Allahu ko si nii fi imo ikoko mo yin, sugbon Allahu yoo sesa eni ti O ba fe ninu awon Ojise Re. Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. Ti e ba gbagbo ni ododo, ti e si beru (Allahu), esan nla yo si wa fun yin

[180] Ki awon t’o n sahun pelu ohun ti Allahu fun won ninu oore-ajulo Re ma se lero pe oore ni fun won. Rara, aburu ni fun won. A o fi ohun ti won fi sahun di won lorun ni Ojo Ajinde. Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[181] Allahu kuku ti gbo oro awon t’o wi pe: “Dajudaju alaini ni Allahu, awa si ni oloro.” A maa sakosile ohun ti won wi ati pipa ti won pa awon Anabi lai letoo. A si maa so pe: “E to iya Ina jonijoni wo.”

[182] Iyen (ri bee) nitori ohun ti owo yin ti siwaju. Ati pe dajudaju Allahu ko nii se abosi fun awon eru (Re)

[183] Awon t’o wi pe: "Dajudaju Allahu sadehun fun wa pe a o gbodo gba Ojise kan gbo titi o maa fi mu saraa kan wa fun wa ti ina (atorunwa) yoo fi lanu." So pe: "Dajudaju awon Ojise kan ti wa ba yin siwaju mi pelu awon eri to yanju ati eyi ti e wi (yii), nitori ki ni e fi pa won ti e ba je olododo

[184] Ti won ba pe o ni opuro, won kuku ti pe awon Ojise t’o siwaju re ni opuro. Won wa pelu awon eri t’o yanju, ipin-ipin Tira ati Tira t’o n tanmole si oro esin

[185] Emi kookan lo maa to iku wo. A o si san yin ni esan yin ni ekunrere ni Ojo Ajinde. Nitori naa, enikeni ti A ba mu jinna tefe si Ina, ti A si mu wo inu Ogba Idera, o kuku ti jere. Ki si ni igbesi aye bi ko se igbadun etan

[186] Dajudaju A o maa dan yin wo ninu dukia yin ati emi yin. Dajudaju eyin yoo maa gbo opolopo oro ipalara lati odo awon ti A fun ni tira siwaju yin ati awon osebo. Ti eyin ba se suuru, ti e si beru (Allahu), dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan

[187] (E ranti) nigba ti Allahu gba adehun awon ti A fun ni tira pe e gbodo se alaye re fun awon eniyan, e o si gbodo fi pamo. Won si ju u seyin leyin won. Won si ta a ni owo kekere. Nitori naa, ohun ti won n ta ma si buru (niya)

[188] E ma se lero pe awon t’o n dunnu si ohun ti won se (ni aidaa maa la ninu iya). Won si nifee si ki awon (eniyan) maa yin won fun ohun ti won ko se (nise rere). Nitori naa, e ma se ro won ro igbala nibi Iya. Iya eleta elero si wa fun won

[189] Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[190] Dajudaju awon ami wa ninu iseda awon sanmo ati ile, itelentele ati iyato oru ati osan; (ami wa ninu won) fun awon onilaakaye

[191] Awon t’o n ranti Allahu ni inaro, ijokoo ati ni idubule; ti won n ronu si iseda awon sanmo ati ile, (won si n so pe:) "Oluwa wa, Iwo ko sedaa eyi pelu iro. Mimo ni fun O. Nitori naa, so wa nibi iya Ina

[192] Oluwa wa, dajudaju enikeni ti O ba mu wo inu Ina, O ti doju ti i. Ko si nii si awon oluranlowo fun awon alabosi

[193] Oluwa wa, dajudaju awa gbo olupepe kan t’o n pe (ipe) si ibi igbagbo pe: "E gba Oluwa yin gbo.” A si gbagbo ni ododo. Oluwa wa, nitori naa, fori awon ese wa jin wa, ki O si pa awon asise wa re, ki O si pa wa pelu awon eni rere

[194] Oluwa wa, fun wa ni ohun ti O sadehun re fun wa lori (ahon) awon Ojise Re. Ma si se doju ti wa ni Ojo Ajinde. Dajudaju Iwo ki i yapa adehun

[195] Oluwa won si jepe won pe: “Dajudaju Emi ko nii fi ise onise kan ninu yin rare; okunrin ni tabi obinrin, ara kan naa ni yin (nibi esan). Nitori naa, awon t’o gbe (ilu won) ju sile, ti won le jade kuro ninu ilu won, ti won si fi inira kan won nitori esin Mi, won jagun esin, won si pa won. Dajudaju Emi yoo ba won pa awon asise won re. Emi yo si mu won wo inu awon Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re. (O je) esan lati odo Allahu. Ni odo Allahu si ni esan daadaa wa

[196] Ma se gba etan pelu igboke-gbodo awon t’o sai gbagbo ninu ilu

[197] Igbadun die (le wa fun won), leyin naa ina Jahanamo ni ibugbe won. Ibugbe naa si buru

[198] Sugbon awon t’o beru Oluwa won, awon Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re n be fun won. Olusegbere ni won ninu re. Ibudesi kan ni lati odo Allahu. Ohun ti n be lodo Allahu si loore julo fun awon eni rere

[199] Dajudaju o n be ninu awon ahlul-kitab eni t’o gbagbo ninu Allahu, ati ohun ti A sokale fun yin ati ohun ti A sokale fun won; won n paya Allahu, won ki i ta awon oro Allahu ni owo kekere. Awon wonyen ni esan lodo Oluwa won. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise

[200] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e se suuru, e parowa suuru, e so bode ilu yin (lati le dena awon omo-ogun ota esin). Ki e si beru Allahu nitori ki e le jere

Àwọn Obìnrin

Surah 4

[1] Eyin eniyan, e beru Oluwa yin, Eni ti O seda yin lati ara emi eyo kan (iyen, Anabi Adam). O si seda aya re (Hawa’) lati ara re. O fon opolopo okunrin ati obinrin jade lati ara awon mejeeji. Ki e si beru Allahu, Eni ti e n fi be ara yin. (E so) okun-ibi. Dajudaju Allahu n je Oluso lori yin

[2] E fun awon omo orukan ni dukia won. E ma se fi nnkan buruku paaro nnkan daadaa. E si ma se je dukia won mo dukia yin; dajudaju o je ese nla

[3] Ti e ba paya pe e o nii se deede nipa (fife) omo orukan, e fe eni t’o letoo si yin ninu awon obinrin; meji tabi meta tabi merin. Sugbon ti e ba paya pe e o nii se deede, (e fe) eyo kan tabi erubinrin yin. Iyen sunmo julo pe e o nii sabosi

[4] E fun awon obinrin ni sodaaki won ni tokan-tokan. Ti won ba si fi inu didun yonda kini kan fun yin ninu re, e je e pelu irorun ati igbadun

[5] E ma se ko dukia yin ti Allahu fi se gbemiiro fun yin le awon alailoye lowo. E pese ije-imu fun won ninu re, ki e si raso fun won. Ki e si maa soro daadaa fun won

[6] E maa sagbeyewo (oye) awon omo orukan titi won yoo fi to igbeyawo se. Ti e ba si ti ri oye lara won, ki e da dukia won pada fun won. E o gbodo je dukia won ni ije apa ati ijekuje ki won to dagba. Eni ti o ba je oloro, ki o moju kuro (nibe). Eni ti o ba je alaini, ki o je ninu re ni ona t’o dara. Nitori naa, ti e ba fe da dukia won pada fun won, e pe awon elerii si won. Allahu si to ni Olusiro

[7] Awon okunrin ni ipin ninu ohun ti obi mejeeji ati ebi fi sile. Ati pe awon obinrin naa ni ipin ninu ohun ti obi mejeeji ati ebi fi sile. Ninu ohun t’o kere ninu re tabi t’o po; (o je) ipin ti won ti pin (fun won)

[8] Nigba ti awon ebi, awon omo orukan ati awon mekunnu ba wa ni (ijokoo) ogun pipin, e fun won ninu re (siwaju ki e to pin ogun), ki e si soro daadaa fun won

[9] Awon (olupingun ati alagbawo omo orukan) ti o ba je pe awon naa maa fi omo wewe sile, ti won si n paya lori won, ki won yaa beru Allahu. Ki won si maa soro daadaa (fun omo orukan)

[10] Dajudaju awon t’o n je dukia omo orukan pelu abosi, Ina kuku ni won n je sinu ikun won. Won si maa wo inu Ina t’o n jo

[11] Allahu n pase fun yin nipa (ogun ti e maa pin fun) awon omo yin; ti okunrin ni iru ipin ti obinrin meji. Ti won ba si je obinrin (nikan) meji soke, tiwon ni ida meji ninu ida meta ohun ti (oku) fi sile. Ti o ba je obinrin kan soso, idaji ni tire. Ti obi re mejeeji, ida kan ninu ida mefa ni ti ikookan awon mejeeji ninu ohun ti oku fi sile, ti o ba ni omo laye. Ti ko ba si ni omo laye, ti o si je pe awon obi re mejeeji l’o maa jogun re, ida kan ninu ida meta ni ti iya re. Ti o ba ni arakunrin (tabi arabinrin), ida kan ninu ida mefa ni ti iya re, (gbogbo re) leyin asoole ti o so tabi gbese. Awon baba yin ati awon omokunrin yin; eyin ko mo ewo ninu won lo maa mu anfaani ba yin julo. (Ipin) oran-anyan ni lati odo Allahu. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon

[12] Tiyin ni ilaji ohun ti awon iyawo yin fi sile, ti won ko ba ni omo. Ti won ba si ni omo, tiyin ni ida kan ninu ida merin ohun ti won fi sile, leyin asoole ti won so tabi gbese. Tiwon si ni ida kan ninu ida merin ohun ti e fi sile, ti eyin ko ba ni omo laye. Ti e ba ni omo laye, ida kan ninu ida mejo ni tiwon ninu ohun ti e fi sile leyin asoole ti e so tabi gbese. Ti okunrin kan tabi obinrin kan ti won fe jogun re ko ba ni obi ati omo, ti o si ni arakunrin kan tabi arabinrin kan, ida kan ninu ida mefa ni ti ikookan awon mejeeji. Ti won ba si po ju bee lo, won yoo dijo pin ida kan ninu ida meta, leyin asoole ti won so tabi gbese, ti ko nii je ipalara. Ofin kan ni lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Alafarada

[13] Iyen ni awon enu-ala (ti) Allahu (gbekale fun ogun pipin). Enikeni ti o ba si tele ti Allahu ati Ojise Re, (Allahu) yoo mu un wo inu awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni erenje nla

[14] Enikeni ti o ba si yapa (ase) Allahu ati Ojise Re, ti o si n tayo awon enu-ala ti Allahu gbekale, (Allahu) yoo mu un wo inu Ina kan. Olusegbere ni ninu re. Iya ti i yepere eda si n be fun un

[15] Awon t’o n se sina ninu awon obinrin yin, e wa elerii merin ninu yin ti o maa jerii le won lori. Ti won ba jerii le won lori, ki e de won mo inu ile titi iku yoo fi pa won tabi (titi) Allahu yoo fi fun won ni ona (miiran)

[16] Awon meji ti won se (sina) ninu yin, ki e (fenu) ba won wi. Ti won ba si ronu piwada, ti won satunse, ki e moju kuro lara won. Dajudaju Allahu n je Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[17] Ironupiwada ti Allahu yoo gba ni ti awon t’o n se ise aburu pelu aimokan. Leyin naa, won ronu piwada laipe. Awon wonyi ni Allahu yoo gba ironupiwada won. Allahu si n je Onimo, Ologbon

[18] Ko si ironupiwada fun awon t’o n se aburu titi iku fi de ba okan ninu won, ki o wa wi pe: “Dajudaju emi ronu piwada nisinsin yii.” (Ko tun si ironupiwada) fun awon t’o ku sipo alaigbagbo. Awon wonyen, A ti pese iya eleta elero sile de won

[19] Eyin ti e gbagbo ni ododo, ko letoo fun yin lati je awon obinrin mogun pelu ipa (bii sisu obinrin lopo.) E ma si di won lowo lati ko apa kan nnkan ti e fun won lo ayafi ti won ba huwa ibaje ponnbele. E ba won lopo pelu daadaa. Ti e ba korira won, o le je pe e korira kini kan, ki Allahu si ti fi opolopo oore sinu re

[20] Ti e ba si fe fi iyawo kan paaro aye iyawo kan, ti e si ti fun okan ninu won ni opolopo dukia, e o gbodo gba nnkan kan ninu re mo. Se eyin yoo gba a ni ti adapa iro (ti e n pa mo won) ati ese to foju han (ti e n da nipa won)

[21] Bawo ni eyin se le gba a pada nigba ti o je pe e ti wole to’ra yin, ti won si ti gba adehun t’o nipon lowo yin

[22] E ma se fe eni ti awon baba yin ti fe ninu awon obinrin ayafi eyi ti o ti re koja. Dajudaju o je iwa ibaje ati ohun ikorira. O si buru ni ona

[23] A se e ni eewo fun yin (lati fe) awon iya yin ati awon omobinrin yin ati awon arabinrin yin ati awon arabinrin baba yin ati awon arabinrin iya yin ati awon omobinrin arakunrin yin ati awon omobinrin arabinrin yin ati awon iya yin ti o fun yin ni oyan mu ati arabinrin yin nipase oyan ati awon iya iyawo yin ati awon omobinrin iyawo yin ti e gba to, eyi t’o wa ninu ile yin, ti e si ti wole to awon iya won, - ti eyin ko ba si ti i wole to won, ko si ese fun yin (lati fe omobinrin won), - ati awon iyawo omo yin, eyi ti o ti ibadi yin jade. (O tun je eewo) lati fe tegbon taburo papo ayafi eyi ti o ti re koja. Dajudaju Allahu, O n je Alaforijin Asake-orun

[24] (O tun je eewo lati fe) awon abileko ninu awon obinrin ayafi awon erubinrin yin. Ofin Allahu niyi lori yin. Won si se eni t’o n be leyin awon wonyen ni eto fun yin pe ki e wa won fe pelu dukia yin; e fe won ni fife iyawo, lai nii ba won se sina (siwaju yigi siso). Eni ti e ba si fe ni fife iyawo, ti e si ti je igbadun oorun ife lara won fun igba die (amo ti e fe ko won sile), e fun won ni sodaaki won. Oran-anyan ni. Ko si si ese fun yin nipa ohun ti e jo yonu si (lati foju fo laaarin ara yin) leyin sodaaki (t’o je oran-anyan). Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon

[25] Eni ti ko ba lagbara oro ninu yin lati fe awon olominira onigbagbo ododo lobinrin, ki o fe ninu awon erubinrin yin, onigbagbo ododo lobinrin. Allahu nimo julo nipa igbagbo yin, ara kan naa (si) ni yin. Nitori naa, e fe won pelu iyonda awon olowo won. Ki e si fun won ni sodaaki won ni ona t’o dara, (iyen) awon omoluabi (erubinrin), yato si awon asewo ati odoko. Nigba ti won ba si di abileko, ti won ba (tun) lo se sina, ilaji iya ti n be fun awon olominira ni iya ti n be fun won. (Fife erubinrin), iyen wa fun eni t’o n paya inira (sina) ninu yin. Ati pe ki e se suuru loore julo fun yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[26] Allahu fe salaye (ofin) fun yin, O fe to yin si ona awon t’o siwaju yin, O si fe gba ironupiwada yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[27] Ati pe Allahu fe gba ironupiwada yin. Awon t’o si n tele ife-adun aye si n fe ki e ye kuro (ninu esin) ni yiye t’o tobi

[28] Allahu fe se irorun fun yin; A si seda eniyan ni ole

[29] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se fi eru je dukia yin laaarin ara yin ayafi ki o je owo sise pelu iyonu laaarin ara yin. E ma se para yin. Dajudaju Allahu n je Alaaanu si yin

[30] Enikeni ti o ba si se iyen lati fi tayo enu-ala ati lati fi se abosi, laipe A maa mu un wo inu Ina. Irorun si ni iyen je fun Allahu

[31] Ti e ba jinna si awon ese nlanla ti A ko fun yin, A maa pa awon iwa aidaa yin re fun yin, A si maa mu yin wo aye alapon-onle

[32] E ma se jerankan ohun ti Allahu fi s’oore ajulo fun apa kan yin lori apa kan. Ipin (esan) n be fun awon okunrin nipa ohun ti won se nise, ipin (esan) si n be fun awon obinrin nipa ohun ti won se nise. Ki e si toro lodo Allahu alekun oore Re. Dajudaju Allahu n je Onimo nipa gbogbo nnkan

[33] Ikookan (awon dukia) ni A ti se adayanri re fun awon ti o maa jogun re ninu ohun ti awon obi ati ebi fi sile. Awon ti e si bura fun (pe e maa fun ni nnkan), e fun won ni ipin won. Dajudaju Allahu n je Elerii lori gbogbo nnkan

[34] Awon okunrin ni opomulero (alase) fun awon obinrin nitori pe Allahu s’oore ajulo fun apa kan won lori apa kan ati nitori ohun ti won n na ninu dukia won. Awon obinrin rere ni awon olutele-ase (Allahu ati ase oko), awon oluso-eto oko ni koro fun wi pe Allahu so (eto tiwon naa fun won lodo oko won). Awon ti e si n paya orikunkun won, e se waasi fun won, e takete si ibusun won, e lu won. Ti won ba si tele ase yin, e ma se fi ona kan wa won nija. Dajudaju Allahu ga, O tobi

[35] Ti e ba si mo pe iyapa wa laaarin awon mejeeji, e gbe oloye kan dide lati inu ebi oko ati oloye kan lati inu ebi iyawo. Ti awon (toko tiyawo) mejeeji ba n fe atunse, Allahu yoo fi awon (oloye mejeeji) se konge atunse lori oro aarin won. Dajudaju Allahu n je Onimo, Alamotan

[36] E josin fun Allahu, e ma se fi nnkan kan sebo si I. E se daadaa si awon obi mejeeji ati ebi ati awon omo orukan ati awon mekunnu ati aladuugbo t’o sunmo ati aladuugbo t’o jinna ati ore alabaarin ati eni ti agara da lori irin-ajo ati awon eru yin. Dajudaju Allahu ko nifee onigbeeraga, afonnu

[37] Awon t’o n sahun, (awon) t’o n pa eniyan lase ahun sise ati (awon) t’o n fi ohun ti Allahu fun won ninu oore ajulo Re pamo; A ti pese iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo

[38] Awon t’o n na owo won pelu sekarimi, ti won ko si gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin; enikeni ti Esu ba je ore fun, o buru ni ore

[39] Ki ni ipalara ti o maa se fun won ti won ba gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti won si na ninu ohun ti Allahu se ni arisiki fun won? Allahu si je Onimo nipa won

[40] Dajudaju Allahu ko nii sabosi odiwon omo ina-igun. Ti o ba je ise rere, O maa sadipele (esan) re. O si maa fun (oluse rere) ni esan nla lati odo Re

[41] Bawo ni oro won yoo ti ri nigba ti A ba mu elerii jade ninu ijo kookan, ti A si mu iwo jade ni elerii lori awon wonyi

[42] Ni ojo yen, awon t’o sai gbagbo, ti won si yapa Ojise, won a fe ki awon ba ile dogba (ki won di erupe). Won ko si le fi oro kan pamo fun Allahu

[43] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se sunmo irun kiki nigba ti oti ba n pa yin titi e maa fi mo ohun ti e n so ati awon onijannaba, afi awon olukoja ninu mosalasi, titi e maa fi we (iwe jannaba). Ti e ba si je alaisan tabi e wa lori irin-ajo tabi okan ninu yin de lati ibi igbonse tabi e sunmo obinrin (yin), ti e ko ri omi, e fi erupe t’o dara se tayamomu; e fi pa oju yin ati owo yin. Dajudaju Allahu n je Alamoojukuro, Alaforijin

[44] Se o o ri awon ti A fun ni ipin kan ninu tira, ti won n ra isina, ti won si fe ki e sina

[45] Allahu si nimo julo nipa awon ota yin. Allahu to ni Alaabo. Allahu si to ni Alaranse

[46] O n be ninu awon yehudi, awon t’o n yi oro pada kuro ni awon aye re, won si n wi pe: “A gbo, a si yapa. Gbo, a o gba tire. Omugo wa.” Won n fi ahon won yi oro sodi ati pe won n bu enu-ate lu esin. ti o ba je pe won so pe: “A gbo, a si tele e. Gbo, ki o si kiye si wa”, iba dara fun won, iba si tona julo. Sugbon Allahu fi won gegun-un nitori aigbagbo won. Nitori naa, won ko nii gbagbo afi die (ninu won)

[47] Eyin ti A fun ni tira, e gbagbo ninu ohun ti A sokale, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa pelu yin, siwaju ki A to fo awon oju kan, A si maa da a pada si (ipako) leyin won, tabi ki A sebi le won gege bi A se sebi le ijo Sabt. Ati pe ase Allahu maa se

[48] Dajudaju Allahu ko nii forijin (eni ti) o ba n sebo si I. O si maa saforijin fun ohun miiran yato si iyen fun eni ti O ba fe. Eni ti o ba n sebo si Allahu, dajudaju o ti da adapa iro (ti o je) ese nla

[49] Se o o ri awon t’o n safomo ara won ni? Ko si ri bee, Allahu l’O n safomo eni ti O ba fe. Ko si nii sabosi bin-intin si won

[50] Wo bi won se n da adapa iro mo Allahu. O si to ni ese ponnbele

[51] Se o o ri awon ti A fun ni ipin kan ninu tira, ti won n gbagbo ninu idan ati orisa, won si n wi fun awon alaigbagbo pe: “Awon (osebo) wonyi mona ju awon t’o gbagbo lododo.”

[52] Awon wonyen ni awon ti Allahu sebi le. Enikeni ti Allahu ba si sebi le, o o nii ri alaranse kan fun un

[53] Tabi ipin kan n be fun won ninu ijoba (Wa) ni? Ti o ba ri bee won ko nii fun awon eniyan ni eekan koro dabinu

[54] Tabi won n se ilara awon eniyan lori ohun ti Allahu fun won ninu oore ajulo Re ni? Dajudaju A fun awon ebi (Anabi) ’Ibrohim ni Tira ati ijinle oye (sunnah). A si fun won ni ijoba t’o tobi

[55] Nitori naa, o n be ninu won eni t’o gbagbo ninu re. O si n be ninu won eni t’o seri kuro nibe. Jahanamo si to ni ina t’o n jo

[56] Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Wa, laipe A maa mu won wo inu Ina. Igbakigba ti awo ara won ba jona, A oo maa paaro awo ara miiran fun won ki won le maa to iya wo lo. Dajudaju Allahu n je Alagbara, Ologbon

[57] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, A oo mu won wo inu awon Ogba Idera kan, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Awon iyawo mimo n be fun won ninu re. A si maa fi won si abe iboji t’o maa siji bo won daradara

[58] Dajudaju Allahu n pa yin ni ase pe ki e da agbafipamo pada fun awon olowo won. Ati pe nigba ti e ba n dajo laaarin awon eniyan, e dajo pelu deede. Dajudaju Allahu n fi nnkan t’o dara se waasi fun yin. Dajudaju Allahu n je Olugbo, Oluriran

[59] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele (ase) Allahu, e tele (ase) Ojise naa ati awon alase ninu yin. Nitori naa, ti e ba yapa enu si kini kan, e seri re si odo Allahu ati Ojise (sollalahu 'alayhi wa sallam), ti e ba gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Iyen loore julo, o si dara julo fun ikangun oro

[60] Se o o ri awon t’o n soro (ti ko si ri bee) pe dajudaju awon gbagbo ninu ohun ti A sokale fun o ati ohun ti A sokale siwaju re, ti won si n gbero lati gbe ejo lo ba orisa, A si ti pa won lase pe ki won lodi si i. Esu si fe si won lona ni isina t’o jinna

[61] Nigba ti won ba so fun won pe: “E wa sibi ohun ti Allahu sokale, e wa ba Ojise.”, o maa ri awon munaafiki ti won yoo maa seri kuro lodo re taara

[62] Bawo ni o se je pe nigba ti adanwo kan ba kan won nipase ohun ti owo won ti siwaju, leyin naa won maa wa ba o, won yo si maa fi Allahu bura pe ko si ohun ti a gba lero bi ko se daadaa ati irepo

[63] Awon wonyen ni awon ti Allahu mo ohun ti n be ninu okan won. Nitori naa, seri kuro lodo won. Se waasi fun won, ki o si ba won so oro t’o lagbara nipa ara won

[64] A o ran Ojise kan nise afi nitori ki won le tele e pelu iyonda Allahu. Ti o ba je pe nigba ti won sabosi si emi ara won, won wa ba o, won si toro aforijin Allahu, ti Ojise si tun ba won toro aforijin, won iba kuku ri Allahu ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[65] Rara, Emi fi Oluwa re bura pe won ko ti i gbagbo ni ododo titi won yoo fi gba o ni oludajo lori ohun ti o ba da yanponyanrin sile laaarin won. Leyin naa, won ko nii ni ehonu kan si idajo ti o ba da. Won si maa gba patapata

[66] Ti o ba je pe A se e ni oran-anyan fun won pe: "E para yin tabi e jade kuro ninu ilu yin," won ko nii se e afi die ninu won. Ti o ba tun je pe won se ohun ti A fi n se waasi fun won ni, iba je oore ati idurosinsin to lagbara julo fun won

[67] Nigba naa, dajudaju Awa iba fun won ni esan nla lati odo Wa

[68] Ati pe dajudaju Awa iba to won si ona taara

[69] Enikeni ti o ba tele (ase) Allahu ati (ase) Ojise naa, awon wonyen maa wa (ninu Ogba Idera) pelu awon ti Allahu sedera fun ninu awon Anabi, awon olododo, awon t’o ku s’oju ogun esin ati awon eni rere. Awon wonyen si dara ni alabaarin

[70] Oore ajulo yen maa wa lati odo Allahu; Allahu si to ni Onimo

[71] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e mu ohun isora yin lowo, ki e si tu jade s’oju ogun esin nikoniko tabi ki e tu jade ni apapo

[72] Dajudaju o n be ninu yin eni t’o n fa seyin. Ti adanwo kan ba kan yin, o maa wi pe: "Allahu kuku ti se idera fun mi nitori pe emi ko si nibe pelu won

[73] Dajudaju ti oore ajulo kan lati odo Allahu ba si te yin lowo, dajudaju o maa soro - bi eni pe ko si ife laaarin eyin ati oun (teletele) - pe: “Yee! Emi iba wa pelu won, emi iba je ere nla.”

[74] Nitori naa, ki awon t’o n fi aye ra orun maa jagun fun esin Allahu. Enikeni ti o ba si jagun nitori esin Allahu, yala won pa a tabi o segun, laipe A maa fun un ni esan nla

[75] Ki l’o se yin ti e o nii jagun fun esin Allahu, nigba ti awon alailagbara ninu awon okunrin, awon obinrin ati awon omode (si n be lori ile), awon t’o n so pe: “Oluwa wa, mu wa jade kuro ninu ilu yii, ilu awon alabosi. Fun wa ni alaabo kan lati odo Re. Ki O si fun wa ni alaranse kan lati odo Re.”

[76] Awon t’o gbagbo ni ododo n jagun fun esin Allahu. Awon t’o sai gbagbo si n jagun fun esin orisa. Nitori naa, e ja awon ore Esu logun. Dajudaju ete Esu, o je ohun ti o le

[77] Se o o ri awon ti A so fun pe: “E da’wo ogun esin duro, e maa kirun (lo na), ki e si maa yo Zakah.” Sugbon nigba ti A se ogun esin jija ni oran-anyan le won lori, igba naa ni apa kan ninu won n beru awon eniyan bi eni ti n beru Allahu tabi ti iberu re le koko julo. Won si wi pe: "Oluwa wa, nitori ki ni O fi se ogun esin jija ni oran-anyan le wa lori? Kuku lo wa lara di igba die si i." So pe: “Bin-intin ni igbadun aye, orun loore julo fun eni t’o ba beru Allahu. A o si nii sabosi bin-intin si yin.”

[78] Ibikibi ti e ba wa, iku yoo pade yin, eyin ibaa wa ninu odi ile giga fiofio. Ti oore (ikogun) kan ba te won lowo, won a wi pe: “Eyi wa lati odo Allahu.” Ti aburu (ifogun) kan ba si sele si won, won a wi pe: “Eyi wa lati odo re.” So pe: “Gbogbo re wa lati odo Allahu.” Ki l’o n se awon eniyan wonyi na, ti won ko fee gbo agboye oro kan

[79] Ohunkohun t’o ba te o lowo ninu oore, lati odo Allahu ni. Ohunkohun ti o ba si sele si o ninu aburu, lati odo ara re ni. A ran o nise pe ki o je Ojise fun awon eniyan. Allahu si to ni Elerii

[80] Enikeni t’o ba tele Ojise naa, o ti tele (ase) Allahu. Enikeni t’o ba si peyinda, A o ran o nise oluso lori won

[81] Won n wi pe: “A tele ase re.” Sugbon nigba ti won ba jade kuro lodo re, igun kan ninu won maa gbimo nnkan ti o yato si eyi ti n so (losan-an). Allahu si n se akosile ohun ti won n gbimo loru. Nitori naa, seri kuro lodo won, ki o si gbarale Allahu. Allahu si to Alaabo

[82] Se won ko ronu nipa al-Ƙur’an ni? Ti o ba je pe o wa lati odo elomiiran yato si Allahu, won iba ri opolopo itakora ninu re

[83] Nigba ti oro ifayabale tabi ipaya kan ba de ba won, won si maa tan an kale. Ti o ba je pe won seri re si (oro) Ojise ati awon alase (iyen, awon onimo esin) ninu won, awon t’o n yo ododo jade ninu oro ninu won iba mo on. Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati aanu Re lori yin ni, eyin iba tele Esu afi iba die (ninu yin)

[84] Nitori naa, jagun fun esin Allahu. Won ko la a bo eni kan lorun afi iwo. Ki o si gbe awon onigbagbo ododo longbe ogun esin jija. O see se ki Allahu ka owoja awon t’o sai gbagbo duro. Ati pe Allahu le julo (nibi) ija. O si le julo nibi ijeni-niya

[85] Enikeni ti o ba sipe isipe rere, o maa ri ipin esan ninu re. Enikeni ti o ba si sipe isipe aburu, o maa ri ipin ese ninu re. Allahu si je Oluso lori gbogbo nnkan

[86] Nigba ti won ba ki yin ni kiki kan, e ki won (pada) pelu eyi t’o dara ju u lo tabi ki e da a pada (pelu bi won se ki yin). Dajudaju Allahu n je Olusiro lori gbogbo nnkan

[87] Allahu, ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun. Dajudaju O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ti ko si iyemeji ninu re. Ta si ni o so ododo ju Allahu lo

[88] Ki ni o maa mu yin pin si ijo meji nipa awon sobe-selu musulumi! Allahu l’O da won pada seyin nitori ohun ti won se nise. Se e fe fi eni ti Allahu si lona mona ni? Enikeni ti Allahu ba si lona, o o nii ri ona kan fun un

[89] Won fe ki e sai gbagbo gege bi won se sai gbagbo, ki e le jo di egbe kan naa. Nitori naa, e ma se mu ore ayo ninu won titi won fi maa si kuro ninu ilu ebo wa si ilu ’Islam fun aabo esin Allahu. Ti won ba keyin (si sise hijrah naa), e mu won, ki e si pa won nibikibi ti e ba ti ri won. Ki e si ma se mu ore ayo ati oluranlowo kan ninu won

[90] Ayafi awon t’o ba dara po mo ijo kan ti adehun n be laaarin eyin ati awon. Tabi won wa ba yin, ti okan won ti pami lati ba yin ja tabi lati ba awon eniyan won ja. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba fun won lagbara (akin-okan) lori yin, won iba si ja yin logun. Nitori naa, ti won ba yera fun yin, ti won ko si ja yin logun, ti won si juwo juse sile fun yin, nigba naa Allahu ko fun yin ni ona lori won (lati ja won logun)

[91] E maa ri awon elomiiran ti won fe fi yin lokan bale, won si fe fi awon eniyan won lokan bale (pe) nigbakigba ti won ba da won pada sinu ifooro (iborisa) ni won n pada sinu re. Ti won ko ba yera fun yin, ti won ko juwo juse sile fun yin, ti won ko si dawo jija yin logun duro, nigba naa e mu won, ki e si pa won nibikibi ti owo yin ba ti ba won. Awon wonyen ni Allahu si fun yin ni agbara t’o yanju lori won (lati ja won logun)

[92] Ko letoo fun onigbagbo ododo kan lati pa onigbagbo ododo kan ayafi ti o ba seesi. Eni ti o ba si seesi pa onigbagbo ododo kan, o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. O si maa san owo emi fun awon eniyan oku afi ti won ba fi tore (fun un). Ti o ba si wa ninu awon eniyan kan ti o je ota fun yin, onigbagbo ododo si ni (eni ti won seesi pa), o maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Ti o ba je ijo ti adehun n be laaarin eyin ati awon, o maa san owo emi fun won. O si maa tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Eni ti ko ba ri eru onigbagbo ododo, o maa gba aawe osu meji ni telentele. (Ona) ironupiwada kan lati odo Allahu (niyi). Allahu n je Onimo, Ologbon

[93] Enikeni ti o ba moomo pa onigbagbo ododo kan, ina Jahanamo ni esan re. Olusegbere ni ninu re. Allahu yoo binu si i. O maa fi sebi le e. O si ti pese iya t’o tobi sile de e

[94] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba wa lori irin-ajo ogun esin Allahu, e se pelepele ki e fi mo ododo (nipa awon eniyan). E si ma se so fun eni ti o ba salamo si yin pe ki i se onigbagbo ododo nitori pe eyin n wa dukia isemi aye. Ni odo Allahu kuku ni opolopo oro ogun wa. Bayen ni eyin naa se wa tele, Allahu si se idera (esin) fun yin. Nitori naa, e se pelepele ki e fi mo ododo (nipa awon eniyan naa). Dajudaju Allahu n je Onimo-ikoko ohun ti e n se nise

[95] Awon olujokoo sinu ile ninu awon onigbagbo ododo, yato si awon alailera, ati awon olujagun fun esin Allahu pelu dukia won ati emi won, won ko dogba. Allahu fi ipo kan soore ajulo fun awon olujagun fun esin Allahu pelu dukia won ati emi won lori awon olujokoo sinu ile. Olukuluku (won) ni Allahu se adehun ohun rere (Ogba Idera) fun. Allahu gbola fun awon olujagun esin lori awon olujokoo sinu ile pelu esan nla

[96] awon ipo kan, aforijin ati aanu lati odo Re. Allahu si n je Alaforijin Asake-orun

[97] Dajudaju awon ti molaika gba emi won, (lasiko) ti won n sabosi si emi ara won, (awon molaika) so pe: “Ki ni e n se (ninu esin)?” Won wi pe: “Won da wa lagara lori ile ni.” (Awon molaika) so pe: “Se ile Allahu ko fe to (fun yin) lati gbe esin yin sa lori ile?” Awon wonyen, ina Jahanamo ni ibugbe won. O si buru ni ikangun

[98] Ayafi awon alailagbara ninu awon okunrin, awon obinrin ati awon omode ti ko ni ikapa ogbon kan, ti won ko si da ona mo (de ilu Modinah)

[99] Nitori naa, awon wonyen, o sunmo ki Allahu samojukuro fun won. Allahu si n je Alamojuukuro, Alaforijin

[100] Enikeni ti o ba gbe ilu re ju sile nitori esin Allahu, o maa ri opolopo ibusasi ati igbalaaye lori ile. Enikeni ti o ba jade kuro ninu ile re (ti o je) olufilu-sile nitori esin Allahu ati Ojise Re, leyin naa ti iku ba a (loju ona), esan re kuku ti wa lodo Allahu. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

[101] Nigba ti e ba se irin-ajo lori ile, ko si ese fun yin lati din irun ku, ti eyin ba n beru pe awon t’o sai gbagbo yoo fooro yin. Dajudaju awon alaigbagbo, won je ota ponnbele fun yin

[102] Nigba ti o ba wa laaarin won, gbe irun duro fun won. Ki igun kan ninu won kirun pelu re, ki won mu nnkan ijagun won lowo. Nigba ti won ba si fori kanle (ti won pari irun), ki won bo seyin yin, ki igun miiran ti ko ti i kirun wa kirun pelu re. Ki won mu isora won ati nnkan ijagun won lowo. Awon t’o sai gbagbo fe ki e gbagbe awon nnkan ijagun yin ati nnkan igbadun yin, ki won le kolu yin ni ee kan naa. Ko si ese fun yin ti o ba je pe ipalara kan n be fun yin latara ojo tabi (pe) e je alaisan, pe ki e fi nnkan ijagun yin sile (lori irun). E mu nnkan isora yin lowo. Dajudaju Allahu ti pese iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo

[103] Nigba ti e ba pari irun, ki e se (gbolohun) iranti Allahu ni iduro, ijokoo ati idubule yin. Nigba ti e ba si fokan bale (iyen nigba ti e ba wonu ilu), ki e kirun (ni pipe). Dajudaju irun kiki je oran-anyan ti A fi akoko si fun awon onigbagbo ododo

[104] E ma se kaaare nipa wiwa awon eniyan naa (lati ja won logun). Ti eyin ba n je irora (ogbe), dajudaju awon naa n je irora (ogbe) gege bi eyin naa se n je irora. Eyin si n reti ohun ti awon ko reti lodo Allahu. Allahu si n je Onimo, Ologbon

[105] Dajudaju Awa so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo nitori ki o le baa sedajo laaarin awon eniyan pelu ohun ti Allahu fi han o. Ma se je olugbeja fun awon onijanba

[106] Toro aforijin lodo Allahu, dajudaju Allahu, O n je Alaforijin, Asake-orun

[107] Ma se ba awon t’o n janba emi ara won wa awijare. Dajudaju Allahu ko feran enikeni ti o je onijanba, elese

[108] Won n fi ara pamo fun awon eniyan, won ko si le fara pamo fun Allahu (nitori pe) O wa pelu won (pelu imo Re) nigba ti won n gbimo ohun ti (Allahu) ko yonu si ninu oro siso. Allahu si n je Alamotan nipa ohun ti won n se nise

[109] Kiye si i, eyin wonyi ni e n ba won mu awijare wa nile aye. Ta ni o maa ba won mu awijare wa ni odo Allahu ni Ojo Ajinde? Tabi ta ni o maa je alaabo fun won

[110] Enikeni ti o ba sise aburu kan tabi ti o sabosi si emi ara re, leyin naa ti o toro aforijin lodo Allahu, o maa ba Allahu ni Alaforijin, Alaaanu

[111] Enikeni ti o ba da ese kan, o da a fun emi ara re. Allahu si n je Onimo, Ologbon

[112] Enikeni ti o ba se asise kan tabi ese kan, leyin naa, o di i ru alaimowo-mese, o ti da oran iparomoni ati ese ponnbele

[113] Ti ki i ba se ti oore ajulo Allahu ati aanu Re ti n be lori re ni, igun kan ninu won iba ti fe si o lona. Won ko si nii si eni kan lona afi ara won. Won ko si le fi nnkan kan ko inira ba o. Allahu si so Tira ati ijinle oye (iyen, sunnah) kale fun o. O tun fi ohun ti iwo ko mo tele mo o; oore ajulo Allahu lori re je ohun t’o tobi

[114] Ko si oore ninu opolopo oro ikoko won afi eni ti o ba pase ore tita tabi ise rere tabi atunse laaarin awon eniyan. Enikeni ti o ba se iyen lati fi wa iyonu Allahu, laipe A maa fun un ni esan t’o tobi

[115] Enikeni ti o ba lodi si Ojise naa leyin ti imona ti foju han si i kedere, ti o tun tele ona t’o yato si ti awon onigbagbo ododo, A oo doju re ko ohun ti o doju ara re ko (ninu isina), A o si mu un wo inu ina Jahanamo. O si buru ni ikangun

[116] Dajudaju Allahu ko nii forijin (eni ti) o ba n sebo si I. O si maa saforijin fun ese miiran yato si iyen fun eni ti O ba fe. Enikeni ti o ba n sebo si Allahu, dajudaju o ti sina ni isina t’o jinna

[117] Won ko pe kini kan leyin Allahu bi ko se awon abo orisa. Won ko si pe kini kan bi ko se Esu oluyapa

[118] Allahu sebi le Esu. O si wi pe: "Dajudaju mo maa mu ipin ti won pin fun mi ninu awon erusin Re

[119] Dajudaju mo maa si won lona. Mo maa fi erokero sinu okan won. Mo maa pa won lase, won yo si maa ge eti eran-osin (lati ya a soto fun orisa). Mo maa pa won lase, won yo si maa yi eda Allahu pada." Enikeni ti o ba mu Esu ni ore leyin Allahu, dajudaju o ti sofo ni ofo ponnbele

[120] Esu n sadehun fun won, o si n fi ife-iro sinu okan won. Esu ko si sadehun kan fun won bi ko se etan

[121] Awon wonyen, ina Jahanamo ni ibugbe won; won ko si nii ri ibusasi kan

[122] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere, A maa mu won wo inu awon Ogba Idera kan, ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. (O je) adehun ti Allahu se ni ti ododo. Ta si ni o so ododo ju Allahu lo

[123] Ki i se ife-okan yin, bee ni ki i se ife-okan awon ahlu-l-kitab (ni osuwon idajo orun. Amo,) enikeni ti o ba sise aburu kan, A oo san an ni esan re; ko si nii ri alafeyinti tabi alaranse kan leyin Allahu

[124] Enikeni ti o ba sise rere, yala okunrin tabi obinrin, onigbagbo ododo si ni, awon wonyen l’o maa wo inu Ogba Idera. A o si nii sabosi eekan koro dabinu fun won

[125] Ta l’o dara ni esin ju eni ti o jura re sile fun Allahu, oluse-rere si tun ni, o tun tele esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-’Islam? Allahu si mu (Anabi) ’Ibrohim ni ayanfe

[126] Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si n je Alamotan nipa gbogbo nnkan

[127] Won n bi o leere idajo nipa awon obinrin. So pe: “Allahu l’O n so idajo won fun yin. Ohun ti won n ke fun yin ninu Tira (al-Ƙur’an naa n so idajo fun yin) nipa awon omo-orukan lobinrin ti e ki i fun ni ohun ti won ko fun won (ninu ogun), ti e tun n soju-kokoro lati fe won ati nipa awon alailagbara ninu awon omode (ti e n je ogun won mole.) ati nipa pe ki e duro ti awon omo orukan pelu deede. Ohunkohun ti e ba si se ni rere, dajudaju Allahu n je Onimo nipa re

[128] Ti obinrin kan ba paya ise orikunkun tabi ikeyinsi lati odo oko re, ko si ese fun awon mejeeji pe ki won se atunse laaarin ara won. Atunse si dara ju lo. Won si ti fi ahun ati okanjua sise sinu emi eniyan. Ti e ba se rere, ti e si beru (Allahu), dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[129] E o le se deede (ninu ife) laaarin awon obinrin, e o baa jerankan re. Nitori naa, e ma se fi sibi kan tan raurau, ki e ma lo pa (eni kan) ti bi ohun agbeko. Ti e ba satunse, ti e si beru (Allahu), dajudaju Allahu n je Alaforijin, Asake-orun

[130] Ti awon mejeeji ba si pinya, Allahu yoo ro ikini keji loro ninu ola Re t’o gbooro. Allahu si n je Olugbooro (ninu oro), Ologbon

[131] Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Dajudaju A ti pa a lase fun awon ti A fun ni tira siwaju yin ati eyin naa pe ki e beru Allahu. Ti e ba si sai gbagbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si n je Oloro, Eleyin (ti eyin to si)

[132] Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si to ni Oluso

[133] Ti (Allahu) ba fe, O maa ko yin kuro lori ile, eyin eniyan. O si maa mu awon miiran wa. Allahu si n je Alagbara lori iyen

[134] Enikeni ti o ba n fe esan nile aye, sebi lodo Allahu ni esan aye ati orun wa. Allahu si n je Olugbo, Oluriran

[135] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je oluduro sinsin lori ododo nigba ti e ba n jerii nitori ti Allahu, koda ki (eri jije naa) tako eyin funra yin tabi awon obi mejeeji ati awon ebi; yala o je oloro tabi alaini. Allahu sunmo (yin) ju awon mejeeji lo. Nitori naa, e ma se tele ife-inu lati ma se deede. Ti e ba yi oju-oro sodi tabi ti e ba gbunri kuro (nibi deede), dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[136] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e gbagbo daadaa ninu Allahu ati Ojise Re, ati Tira ti (Allahu) sokale fun Ojise Re, ati Tira ti O sokale siwaju. Enikeni ti o ba sai gbagbo ninu Allahu, awon molaika Re, awon Tira Re, awon Ojise Re ati Ojo Ikeyin, dajudaju o ti sina ni isina t’o jinna tefetefe

[137] Dajudaju awon t’o gbagbo, leyin naa won sai gbagbo, leyin naa won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo, leyin naa won si lekun si i ninu aigbagbo, Allahu ko nii fori jin won, ko si nii fi ona mo won

[138] Fun awon sobe-selu musulumi ni iro pe dajudaju iya eleta elero n be fun won

[139] (Awon ni) awon t’o n mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo. Se e n wa agbara lodo won ni? Dajudaju ti Allahu ni gbogbo agbara patapata

[140] (Allahu) kuku ti so o kale fun yin ninu Tira pe nigba ti e ba gbo nipa awon ayah Allahu pe won n sai gbagbo ninu re, won si n fi se efe, e ma se jokoo ti won nigba naa titi won yoo fi bo sinu oro miiran, bi bee ko dajudaju eyin yoo da bi iru won. Dajudaju Allahu yoo pa awon sobe-selu musulumi po mo gbogbo awon alaigbagbo ninu ina Jahanamo

[141] (Awon ni) awon t’o fe yo yin; ti isegun kan lati odo Allahu ba je tiyin, won a wi pe: “Se awa ko wa pelu yin bi?” Ti ipin kan ba si wa fun awon alaigbagbo, (awon munaafiki) a wi pe: “Se awa ko ti ni ikapa lati je gaba le yin lori (amo ti awa ko se bee), se awa ko si daabo bo yin to lowo awon onigbagbo ododo (titi owo yin fi ba oro-ogun, nitori naa ki ni ipin tiwa ti e fe fun wa?)” Nitori naa, Allahu yoo sedajo laaarin yin ni Ojo Ajinde. Allahu ko si nii fun awon alaigbagbo ni ona (isegun) kan lori awon onigbagbo ododo

[142] Dajudaju awon sobe-selu musulumi n tan Allahu, Oun naa si maa tan won. Nigba ti won ba duro lati kirun, won a duro (ni iduro) oroju, won yo si maa se sekarimi (lori irun). Won ko si nii se (gbolohun) iranti Allahu (lori irun) afi die

[143] Won n se balabala sihin-in sohun-un, won ko je ti awon wonyi, won ko si je ti awon wonyi. Enikeni ti Allahu ba si lona, o o si nii ri ona kan fun un

[144] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo (egbe yin). Se e fe se nnkan ti Allahu yoo fi ni eri ponnbele lowo lati je yin niya ni

[145] Dajudaju awon sobe-selu musulumi yoo wa ninu aja isale patapata ninu Ina. O o si nii ri alaranse kan fun won

[146] Ayafi awon t’o ronu piwada, ti won se atunse, ti won duro sinsin ti Allahu, ti won si se afomo esin won fun Allahu. Nitori naa, awon wonyen maa wa pelu awon onigbagbo ododo. Laipe Allahu maa fun awon onigbagbo ododo ni esan nla

[147] Ki ni Allahu maa fi iya yin se, ti e ba dupe, ti e si gbagbo ni ododo? Allahu si n je Olumoore, Onimo

[148] Allahu ko nifee si ariwo epe sise (lati odo enikeni) ayafi eni ti won ba se abosi si. Allahu si n je Olugbo, Onimo

[149] Ti e ba safi han rere tabi e fi pamo tabi e samoju kuro nibi aburu, dajudaju Allahu n je Alamojuukuro, Alagbara

[150] Dajudaju awon t’o n sai gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re, ti won fe sopinya laaarin Allahu ati awon Ojise Re, ti won si n wi pe: “A gbagbo ninu apa kan, a si sai gbagbo ninu apa kan,” won si fe mu ona kan to (lesin) laaarin iyen

[151] Ni ododo, awon wonyen, awon ni alaigbagbo. A si ti pese Iya ti i yepere eda sile de awon alaigbagbo

[152] Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re, ti won ko si ya eni kan soto ninu won, laipe awon wonyen, (Allahu) maa fun won ni esan won. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

[153] Awon ahlul-kitab n bi o leere pe ki o so tira kan kale lati inu sanmo. Won kuku bi (Anabi) Musa ni ohun ti o tobi ju iyen lo. Won wi pe: “Fi Allahu han wa ni gbangba.” Nitori naa, ohun igbe lati inu sanmo gba won mu nipase abosi owo won. Leyin naa, won tun so oborogidi omo maalu di nnkan ti won josin fun leyin ti awon eri t’o yanju ti de ba won. A tun samoju kuro nibi iyen. A si fun (Anabi) Musa ni eri ponnbele

[154] A gbe apata soke ori won nitori majemu won. A si so fun won pe: “E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba.” A tun so fun won pe: “E ma se tayo enu-ala ni ojo Sabt.” A si gba adehun t’o nipon lowo won

[155] Nitori yiye ti won funra won ye adehun won, sisaigbagbo won ninu awon oro Allahu, pipa ti won n pa awon Anabi lai letoo ati wiwi ti won n wi pe: “Okan wa ti di.” – rara, Allahu ti fi edidi di okan won ni nitori aigbagbo won. – Nitori naa, won ko nii gbagbo afi die (ninu won)

[156] Ati nitori aigbagbo won ati oro won lori Moryam ni ti ibanilorukoje t’o tobi (Allahu tun fi edidi di okan won)

[157] Ati nitori oro won (yii): “Dajudaju awa pa Mosih, ‘Isa omo Moryam, Ojise Allahu.” Won ko pa a, won ko si kan an mo agbelebuu, sugbon A gbe aworan re wo elomiiran fun won ni. Dajudaju awon t’o yapa-enu nipa re, kuku wa ninu iyemeji ninu re; ko si imo kan fun won nipa re afi titele erokero. Won ko pa a ni amodaju. surah ali ‘Imron; 3:7 surah al-’Ani‘am; 6: 99 ati

[158] Rara o, Allahu gbe e wa soke lodo Re ni. Allahu si n je Alagbara, Ologbon

[159] Ko si nii si eni kan ninu awon ahlul-kitab (laye nigba ti ‘Isa ba sokale pada lati oju sanmo) afi ki o gba a gbo ni ododo siwaju iku re. Ni Ojo Ajinde, o si maa je elerii lori won. agbega ipo gege bi eyi t’o jeyo ninu surah Al-’a‘rof; 7:176 ati surah Moryam; 19:57) tabi ki o tumo si agbega tara (iyen gbigbe ara kuro lati aye isale si aye oke gege bi eyi t’o jeyo ninu surah Fatir; 35:10). Amo ko ni tabi-sugbon ninu mo pe nigbakigba ti harafi “إلى” ba ti tele “رفع” oke sanmo keje ni Allahu wa nitori pe inu sanmo yii naa ni Anabi wa Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) gun lo lati lo gba irun wakati marun-un wa lodo Allahu (subhanahu wa ta'ala) lasiko irin oru ati igun-sanmo gege bi Allahu se fi rinle ni ibere surah al-’Isro’. Koda tohun ti bi aigbagbo Fir‘aon se gbopon to o kuku gba pe sanmo ni Allahu (subhanahu wa ta'ala) wa. O si be Hamon ni ile giga fiofio ko. O fe yoju wo Allahu! (surah al-Ƙosos; 28:38). Nitori naa

[160] Nitori abosi lati odo awon ti won di yehudi, A se awon nnkan daadaa kan ni eewo fun won, eyi ti won se ni eto fun won (tele. A se e ni eewo fun won se) nipa bi won se n seri opolopo kuro loju ona (esin) Allahu

[161] Ati gbigba ti won n gba owo ele, ti A si ti ko o fun won, ati jije ti won n je dukia awon eniyan lona eru. A si ti pese iya eleta-elero sile de awon alaigbagbo

[162] Sugbon awon agba ninu imo ninu won ati awon onigbagbo ododo, won gbagbo ninu ohun ti A sokale fun o ati ohun ti A sokale siwaju re, (won tun gbagbo ninu awon molaika) t’o n kirun. (Awon wonyen) ati awon t’o n yo Zakah ati awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, awon wonyen ni A maa fun ni esan nla

[163] Dajudaju Awa (fi imisi) ranse si o gege bi A se fi ranse si (Anabi) Nuh ati awon Anabi (miiran) leyin re. A fi imisi ranse si (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo (re), ati (Anabi) ‘Isa, ’Ayyub, Yunus, Harun ati Sulaemon. A si fun (Anabi) Dawud ni Zabur

[164] Ati awon Ojise kan ti A ti so itan won fun o siwaju pelu awon Ojise kan ti A ko so itan won fun o. Allahu si ba (Anabi) Musa soro taara

[165] (A se won ni) Ojise, oniroo idunnu ati olukilo nitori ki awijare ma le wa fun awon eniyan lodo Allahu leyin (ti) awon Ojise (ti jise). Allahu si n je Alagbara, Ologbon

[166] Sugbon Allahu n jerii si ohun ti O sokale fun o. O so o kale pelu imo Re. Awon molaika naa n jerii (si i). Allahu si to ni Elerii

[167] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won kuku ti sina ni isina t’o jinna

[168] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won tun sabosi, Allahu ko nii fori jin won, ko si nii fi oju-ona mo won

[169] Ayafi oju-ona ina Jahanamo. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen si n je irorun fun Allahu

[170] Eyin eniyan, dajudaju Ojise naa ti de ba yin pelu ododo lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ki e gba a gbo l’o dara julo fun yin. Ti e ba si sai gbagbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Allahu si n je Onimo, Ologbon

[171] Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ki e si ma so ohun kan nipa Allahu afi ododo. Ojise Allahu ni Mosih ‘Isa omo Moryam. Oro Re (kun fayakun) ti O so ranse si Moryam l’O si fi seda re. Emi kan (ti Allahu seda) lati odo Re si ni (Mosih ‘Isa omo Moryam). Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. E ye so meta (lokan) mo. Ki e jawo nibe lo je oore fun yin. Allahu nikan ni Olohun, Okan soso (ti ijosin to si). O mo tayo ki O ni omo. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si to ni Alamojuuto

[172] Mosih ko ko lati je eru fun Allahu. Bee naa ni awon molaika ti won sunmo Allahu. Enikeni ti o ba ko lati josin fun Un, ti o tun segberaga, (Allahu) yoo ko won jo papo patapata si odo Re

[173] Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere, (Allahu) yoo san won ni esan rere won. O si maa se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Ni ti awon t’o ba si ko (lati josin fun Allahu), ti won si segberaga, (Allahu) yoo je won niya eleta-elero. Won ko si nii ri alatileyin tabi alaranse kan leyin Allahu

[174] Eyin eniyan, dajudaju eri oro ti de ba yin lati odo Oluwa yin. A si tun so imole t’o yanju kale fun yin

[175] Ni ti awon t’o gbagbo ninu Allahu, ti won si duro sinsin ti I, O maa fi won sinu ike ati ola kan lati odo Re. O si maa fi won mo ona taara si odo Re

[176] Won n bi o leere ibeere, so pe: “Allahu n fun yin ni idajo nipa eni ti ko ni obi, ko si ni omo. Ti eniyan kan ba ku, ti ko ni omo laye, ti o si ni arabinrin kan, idaji ni tire ninu ohun ti o fi sile. (Arakunrin) l’o maa je gbogbo ogun arabinrin re, ti ko ba ni omo laye. Ti arabinrin ba si je meji, ida meji ninu ida meta ni tiwon ninu ohun ti o fi sile. Ti won ba si je arakunrin (pupo) lokunrin ati lobinrin, ti okunrin kan ni ipin obinrin meji. Allahu n se alaye fun yin ki e ma baa sina. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

Oúnjẹ

Surah 5

[1] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e mu awon adehun se. Won se awon eran-osin ni eto fun yin afi eyi ti won ba n ka fun yin (ni eewo), lai nii so idode eranko di eto nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. Dajudaju Allahu n se idajo ohun ti O ba fe

[2] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se ru ofin awon nnkan arisami ti Allahu gbe kale fun esin Re. E ma se so osu owo di eto (fun ogun esin), E ma se idiwo fun awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. E ma se idiwo fun awon t’o n gbero lati lo si Ile Haram, ti won n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Oluwa won. Ti e ba si ti tura sile ninu aso hurumi, nigba naa e (le) dode (eranko). E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati tayo enu-ala nitori pe won se yin lori kuro ni Mosalasi Haram. E ran ara yin lowo lori ise rere ati iberu Allahu. E ma se ran ara yin lowo lori (iwa) ese ati itayo enu-ala. E beru Allahu. Dajudaju Allahu le (nibi) iya

[3] A se e ni eewo fun yin eran okunbete, ati eje, ati eran elede, ati eyi ti won pa pelu oruko ti ki i se Allahu, ati eran ti won fun lorun pa, ati eran ti won lu pa, ati eran ti o re lule ku, ati eran ti won kan pa ati eyi ti eranko abijawara je ku afi eyi ti e ba ri du (siwaju ki o to ku) ati eyi ti won pa sidii orisa. Eewo si ni fun yin lati yese wo. Iwonyi ni ibaje. Lonii ni awon t’o sai gbagbo soreti nu nipa esin yin. Nitori naa, e ma se paya won. E paya Mi. Mo pari esin yin fun yin lonii. Mo si se asepe idera Mi fun yin. Mo si yonu si ’Islam ni esin fun yin. Nitori naa, enikeni ti won ba ko sinu inira ebi (lati je eran eewo), yato si olufinnufindo-dese, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[4] Won n bi o leere pe: "Ki ni Won se ni eto fun won?" So pe: “Won se awon nnkan daadaa ni eto fun yin ati (eran ti e pa nipase) eyi ti e ko ni eko (idode) ninu awon eranko ati eye ti n dode. E ko awon aja lekoo idode, ki e ko won ninu ohun ti Allahu fi mo yin. Nitori naa, e je ninu ohun ti won ba pa fun yin, ki e si se bismillah si i . E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise

[5] Won se awon nnkan daadaa ni eto fun yin lonii. Ati ounje awon ti A fun ni tira, eto ni fun yin.1 Ounje tiyin naa, eto ni fun won. (Eto ni fun yin lati fe) awon olominira ninu awon onigbagbo ododo lobinrin ati awon olominira lobinrin ninu awon ti A fun ni tira siwaju yin, nigba ti e ba ti fun won ni sodaaki won; e fe won ni fife (bi ’Islam se ni ki e fe iyawo), lai nii ba won se sina (siwaju yigi) lai si nii yan won lale.2 Enikeni ti o ba lodi si igbagbo ododo, ise re ti baje. Ni Ojo Ikeyin, o si maa wa ninu awon eni ofo. orisa ibere ati idawole kan ti awon oyinbo aborisa n pe ni Janus ni won fi gbe osu ati odun January kale. Awon kristieni si tewo gba a lowo won. Musulumi yo si maa je musulumi lori gbigba oro Allahu gbo ni ododo. Ti iru musulumi yii ba tun wa ba awon kristieni da si odun January lai si siju wo awon ewu nla ti ko se e janiyan t’o tun ro mo igbeyawo. Dandan si ni fun wa lati lo ayah papo mora won ni ona ti ko fi nii ja si pe musulumi tele itumo oju-oro nikan ni iyapa si itumo oju oro miiran. Ni akoko na ninu surah al-Baƙorah

[6] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba fe kirun, e we oju yin ati owo yin titi de igunpa. E fi omi pa ori yin. E we ese yin titi de kokose mejeeji. Ti e ba ni jannaba lara, e we iwe imora. Ti e ba je alaisan, tabi e n be lori irin-ajo tabi eni kan ninu yin de lati ile igbonse, tabi e sunmo obinrin, ti e o ba ri omi, nigba naa ki e fi erupe mimo se tayamomu. E fi pa oju yin ati owo yin lara re. Allahu ko fe lati ko wahala ba yin, sugbon O fe lati fo yin mo. O si fe se asepe idera Re fun yin nitori ki e le dupe

[7] E ranti idera ti Allahu se fun yin ati adehun Re, eyi ti O ba yin se, nigba ti eyin so pe: “A gbo, a si tele e.” E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda

[8] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nitori ti Allahu e je oluduro sinsin lori ododo nigba ti e ba n jerii. E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati ma se deede. E se deede, ohun l’o sunmo iberu Allahu julo. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[9] Allahu se adehun fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere (pe) aforijin ati esan nla n be fun won

[10] Awon t’o sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim

[11] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti idera ti Allahu se fun yin; nigba ti ijo kan gbero lati nawo ija si yin, (Allahu) si ko won lowo ro fun yin. E beru Allahu. Ati pe Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

[12] Dajudaju Allahu gba adehun lowo awon omo ’Isro’il. A si gbe ijoye mejila dide ninu won. Allahu si so fun won pe: “Dajudaju Mo n be pelu yin, ti e ba n kirun, ti e ba n yo Zakah, ti e ba n gba awon Ojise Mi gbo, ti e ba n ran won lowo, ti e ba n ya Allahu ni dukia t’o dara. Dajudaju Mo maa pa awon asise yin re. Dajudaju Mo maa mu yin wo inu awon Ogba Idera kan, ti odo n san ni isale re. Amo enikeni ti o ba sai gbagbo leyin iyen ninu yin, o ti sina kuro loju ona.”

[13] Nitori yiye ti won funra won ye adehun won ni A fi sebi le won. A si mu okan won le koko (nitori pe) won n gbe awon oro kuro ni awon aye re, won si gbagbe ipin kan ninu oore ti A fi se iranti fun won. O o nii ye ri onijanba laaarin won afi die ninu won. Nitori naa, se amojukuro fun won, ki o si fori jin won. Dajudaju Allahu feran awon oluse-rere

[14] Ati pe lodo awon t’o wi pe: “Dajudaju nasara ni awa.”, A gba adehun lowo won, won si gbagbe ipin kan ninu oore ti A fi se iranti fun won. Nitori naa, A gbin ota ati ote saaarin won titi di Ojo Ajinde. Laipe Allahu maa fun won ni iro ohun ti won n se nise

[15] Eyin ahlul-kitab, dajudaju Ojise Wa ti wa ba yin. O n salaye opolopo ohun ti e fi pamo ninu tira fun yin. O si n samojukuro nibi opolopo. Imole ati Tira t’o yanju kuku ti de ba yin lati odo Allahu

[16] Allahu n fi (al-Ƙur’an) se imona fun enikeni ti o ba tele (awon nnkan) ti Allahu yonu si, awon ona alaafia. (Allahu) yo si mu won jade lati inu awon okunkun wa sinu imole pelu iyonda Re. O si maa to won si ona taara (’Islam)

[17] Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Mosih omo Moryam.” So pe: “Ta si l’o ni ikapa kini kan lodo Allahu ti (Allahu) ba fe pa Mosih omo Moryam, ati iya re ati awon t’o n be lori ile aye run patapata?” Ti Allahu ni ijoba awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. (Allahu) n sedaa ohunkohun ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[18] Awon yehudi ati nasara wi pe: "Awa ni omo Allahu ati ololufe Re." So pe: “Ki ni idi ti O se n fi iya ese yin je yin nigba naa?” Rara (ko ri bi e se wi, amo) abara ni yin ninu awon ti O seda. O n saforijin fun eni ti O ba fe. O si n je eni ti O ba fe niya. Ti Allahu ni ijoba awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Odo Re si ni abo eda

[19] Eyin ahlul-kitab, dajudaju Ojise Wa ti de ba yin, ti o n se alaye (oro) fun yin leyin asiko ti A ti da awon Ojise duro, nitori ki e ma baa wi pe: “Ko si oniroo idunnu tabi olukilo kan ti o de ba wa.” Nitori naa, dajudaju oniroo idunnu ati olukilo kan ti de ba yin. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[20] Nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "Eyin ijo mi, e ranti idera ti Allahu se fun yin, nigba ti O fi awon Anabi saaarin yin, ti O se yin ni oba, ti O tun fun yin ni nnkan ti ko fun eni kan ri ni agbaye (lasiko tiyin)

[21] Eyin ijo mi, e wo ori ile mimo ti Allahu ko mo yin. E ma se pada seyin, nitori ki e ma baa pada di eni ofo

[22] Won wi pe: "Musa, dajudaju ijo ajeni-nipa wa ninu ilu naa. Dajudaju awa ko si nii wo inu re titi won yoo fi jade kuro ninu re. Ti won ba jade kuro ninu re, awa maa wo inu re nigba naa

[23] Awon okunrin meji kan ninu awon ti n paya (Allahu) - Allahu si ke awon mejeeji - won so pe: "E gba enu bode wo inu ilu to won. Ti e ba wo inu ilu to won, dajudaju e maa bori won. Allahu si ni ki e gbarale, ti e ba je onigbagbo ododo

[24] Won wi pe: "Iwo Musa, dajudaju awa ko nii wo inu ilu naa laelae niwon igba ti won ba si wa ninu re. Nitori naa, ki iwo ati Oluwa re lo. Ki eyin mejeeji ja won logun. Dajudaju ibi yii ni awa yoo jokoo si na

[25] O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi ko ni ikapa lori eni kan bi ko se (lori) ara mi ati arakunrin mi. Nitori naa, ya awa ati ijo obileje si otooto

[26] (Allahu) so pe: “Dajudaju o ti di eewo fun won (lati wo inu ilu naa) fun ogoji odun ti won yoo fi maa rin rin rin lori ile. Nitori naa, ma se banuje nitori ijo obileje.”

[27] Ka oro awon omo (Anabi) Adam mejeeji fun won pelu ododo. (Ranti) nigba ti awon mejeeji se itore ase (lati fi sunmo Allahu). Won gba ti okan ninu awon mejeeji, Won ko si gba ti ikeji. (Eni ti Won ko gba tire) wi pe: “Dajudaju emi yoo pa o.” (Ikeji) si so pe: "(Ore) tawon oluberu nikan ni Allahu maa gba

[28] Dajudaju ti o ba na owo re si mi lati pa mi, emi ko si nii na owo mi si o lati pa o, nitori pe emi n beru Allahu, Oluwa gbogbo eda

[29] Dajudaju emi fe ki o pada (si odo Allahu ni Ojo Ajinde) pelu ese (bi o se pa) mi ati ese tire nitori ki o le je okan ninu awon ero inu Ina. Iyen si ni esan awon alabosi

[30] Emi re si gba fun un lati pa arakunrin re. O pa a. O si di okan ninu awon eni ofo

[31] Allahu si gbe eye kannakanna kan dide. O si n fi ese wa ile nitori ki o le fi bi o se maa bo oku arakunrin re mo inu ile han an. O wi pe: “Temi baje o! Mo kagara lati da bi iru eye kannakanna yii, ki ng si le bo oku arakunrin mi mole.” O si di ara awon alabaamo

[32] Nitori iyen, A si se e ni ofin fun awon omo ’Isro’il pe dajudaju enikeni ti o ba pa emi (eniyan) kan laije nitori pipa emi (eniyan) kan tabi sise ibaje kan lori ile, o da bi eni ti o pa gbogbo eniyan patapata. Enikeni ti o ba si mu emi (eniyan) semi, o da bi eni ti o mu gbogbo eniyan semi patapata. Awon Ojise Wa si ti wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Leyin naa, dajudaju opolopo ninu won leyin iyen ni alakoyo lori ile

[33] Esan awon t’o n gbogun ti Allahu ati Ojise Re, ti won si n se ibaje lori ile ni pe, ki e pa won tabi ki e kan won mo igi agbelebuu tabi ki e ge owo won ati ese won ni ipasipayo tabi ki e le won kuro ninu ilu. Iyen ni iyepere fun won nile aye. Iya nla si n be fun won ni orun

[34] Ayafi awon t’o ronu piwada siwaju ki e to lagbara lori won. Nitori naa, e mo pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[35] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si wa ategun si odo Re (pelu ise rere). E jagun fun esin Re nitori ki e le jere

[36] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti o ba je pe gbogbo ohun ti n be lori ile aye patapata je tiwon ati iru re pelu re lati fi gba ara won sile nibi iya Ojo Ajinde, A o nii gba a ni owo won. Iya eleta-elero si wa fun won

[37] Won yoo fe jade kuro ninu Ina, won ko si nii le jade kuro ninu re. Iya gbere si wa fun won

[38] Ole lokunrin ati ole lobinrin, e ge owo awon mejeeji. (O je) esan fun ise owo awon mejeeji. (O si je) ijiya lati odo Allahu. Allahu si ni Alagbara, Ologbon

[39] Enikeni ti o ba ronu piwada leyin abosi (owo) re, ti o si se atunse, dajudaju Allahu yoo gba ironupiwada re. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Alaaanu

[40] Se o o mo pe dajudaju ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile? O maa je eni ti O ba fe niya. O si maa fori jin eni ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[41] Iwo Ojise, ma se je ki o ba o ninu je awon t’o n yara lo sinu aigbagbo ninu awon t’o fi enu ara won wi pe: “A gbagbo.” – ti okan won ko si gbagbo ni ododo - ati awon t’o di yehudi, ti won n teti si iro, ti won si n teti si oro fun awon eniyan miiran ti ko wa si odo re, ti won n yi oro pada kuro ni awon aye re, won si n wi pe: “Ti won ba fun yin ni eyi e gba a. Ti won ko ba si fun yin e sora.” Enikeni ti Allahu ba fe fooro re, o o ni ikapa kini kan lodo Allahu fun un. Awon wonyen ni awon ti Allahu ko fe fo okan won mo. Idojuti n be fun won ni aye. Iya nla si n be fun won ni orun

[42] Won n teti gbo iro, won si n je nnkan eewo. Nitori naa, ti won ba wa ba o, sedajo laaarin won tabi ki o seri kuro lodo won. Ti o ba seri kuro lodo won, won ko le ko inira kan kan ba o. Ti o ba si fe dajo, se idajo laaarin won pelu deede. Dajudaju Allahu nifee awon onideede

[43] Bawo ni won a se fi o se adajo, nigba ti o je pe Taorah wa lodo won. Idajo Allahu si wa ninu re. Leyin naa, won n peyin da leyin iyen. Awon wonyen ki i si se onigbagbo ododo

[44] Dajudaju Awa so Taorah kale. Imona ati imole n be ninu re. Awon Anabi ti won je musulumi n fi se idajo fun awon t’o di yehudi. Bee naa ni awon alufaa ati awon amofin (n fi se idajo) nitori ohun ti A ni ki won so ninu tira Allahu. Won si je elerii lori re. Nitori naa, ma se paya eniyan. E paya Mi. E ma se ta awon ayah Mi ni owo kekere. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni alaigbagbo

[45] A si se e ni ofin sinu re pe dajudaju emi fun emi, oju fun oju, imu fun imu, eti fun eti ati eyin fun eyin. Ofin esan gbigba si wa fun oju-ogbe. Enikeni ti o ba si yonda igbesan, o si maa je ipesere fun un. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni alabosi

[46] A fi ‘Isa omo Moryam tele oripa won (iyen, awon Anabi ti won je musulumi); ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re ninu Taorah. A si fun un ni ’Injil. Imona ati imole wa ninu re, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re ninu Taorah. (O je) imona ati waasi fun awon oluberu (Allahu ni asiko tire)

[47] Ki awon ti A fun ni ’Injil sedajo pelu ohun ti Allahu sokale ninu re. Enikeni ti ko ba sedajo pelu ohun ti Allahu sokale, awon wonyen ni obileje

[48] A so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. O n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ninu Tira. O n wa aabo fun awon ofin inu re. Nitori naa, fi ohun ti Allahu sokale dajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won t’o yapa si ohun ti o de ba o ninu ododo. Olukuluku ninu yin ni A ti se ofin ati ilana fun. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin ni. Nitori naa, e gbawaju nibi ise rere. Odo Allahu ni ibupadasi gbogbo yin patapata. O si maa fun yin ni iro nipa ohun ti e n yapa enu si

[49] Ati pe ki o fi ohun ti Allahu sokale se idajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won. Sora fun won ki won ma baa fooro re kuro nibi apa kan ohun ti Allahu sokale fun o. Ti won ba si gbunri, mo pe Allahu kan fe fi adanwo kan won ni nitori apa kan ese won. Ati pe dajudaju opolopo ninu eniyan ni obileje

[50] Se idajo igba aimokan ni won n wa ni? Ta ni eni ti o dara ju Allahu lo nibi idajo fun ijo t’o ni amodaju (nipa Re)

[51] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon yehudi ati nasara ni ore ayo. Apa kan won lore apa kan. Enikeni ti o ba mu won ni ore ayo ninu yin, dajudaju o ti di ara won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

[52] Nitori naa, o maa ri awon ti aare wa ninu okan won, ti won yoo maa yara lo saaarin won. Won yoo maa wi pe: “A n beru pe ki apadasi igba ma baa kan wa ni.” O sunmo ki Allahu mu isegun tabi ase kan wa lati odo Re. Won yo si di alabaamo lori ohun ti won fi pamo sinu okan won

[53] Awon t’o gbagbo ni ododo si maa so pe: "Se awon (yehudi) wonyi ko ni awon t’o fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe dajudaju awon n be pelu eyin (munafiki)?" Ise won ti baje. Nitori naa, won si di eni ofo

[54] Eyin ti e gbagbo ni ododo, enikeni ti o ba peyinda nibi esin re ninu yin, laipe Allahu maa mu awon eniyan kan wa; O maa nifee won, awon naa maa nifee Re. Won yoo ro fun awon onigbagbo ododo. Won yo si le mo awon alaigbagbo. Won yoo maa jagun esin fun Allahu. Won ko si nii beru eebu eleeebu. Iyen ni oore ajulo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Olugbooro, Onimo

[55] Allahu ati Ojise Re ati awon t’o gbagbo ni ododo nikan ni ore yin, awon t’o n kirun, ti won si n yo Zakah, awon si ni oludawote-orunkun (lori irun)

[56] Enikeni ti o ba mu Allahu ati Ojise Re ati awon onigbagbo ododo ni ore; dajudaju ijo Allahu, awon ni olubori

[57] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon t’o so esin yin di nnkan yeye ati ere sise ni ore ninu awon ti A fun ni tira siwaju yin ati awon alaigbagbo. E beru Allahu ti e ba je onigbagbo ododo

[58] Nigba ti e ba pepe sibi irun kiki, won yoo so o di nnkan yeye ati ere sise. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko se laakaye

[59] So pe: “Eyin ahlul-kitab, nje e tako kini kan lara wa bi ko se pe a gbagbo ninu Allahu ati ohun ti Won sokale fun wa ati ohun ti Won sokale siwaju?” Dajudaju opolopo yin ni obileje

[60] So pe: “Se ki ng fun yin ni iro awon ti iya won buru ju iyen lo ni odo Allahu?” (Oun ni) eni ti Allahu sebi le, ti O si binu si, ti O si so awon kan ninu won di obo, elede ati aborisa. Awon wonyen ni ipo won buru julo, awon si ni won sina julo

[61] Nigba ti won ba wa si odo yin, won a wi pe: “A gbagbo.” Dajudaju won wole (ti yin) pelu aigbagbo, won si ti jade pelu re. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo

[62] O maa ri opolopo ninu won, ti won n yara ko sinu ese, itayo enu-ala ati jije ti won n je owo eru. Dajudaju ohun ti won n se nise buru

[63] Ki ni ko je ki awon alufaa ati awon amofin maa ko fun won nipa oro enu won (ti o je) ese ati jije ti won n je owo eru! Dajudaju ohun ti won n se nise buru

[64] Awon yehudi wi pe: "Owo Allahu wa ni didi pa." A di owo won pa. A si sebi le won nitori ohun ti won wi. Amo owo Re mejeeji wa ni tite sile. O si n tore bi O se fe. Ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa Re yoo kuku je ki opolopo won lekun ni igberaga ati aigbagbo ni. A si ju ota ati ikorira saaarin won titi di Ojo Ajinde. Igbakigba ti won ba dana ogun, Allahu si maa pana re. Won si n se ibaje lori ile. Allahu ko si nifee awon obileje

[65] Ti o ba je pe dajudaju awon ahlul-kitab gbagbo ni ododo, ki won si beru (Allahu), Awa iba pa awon aida won re fun won, Awa iba si mu won wo inu awon Ogba Idera

[66] Ti o ba je pe dajudaju won lo at-Taorah ati al-’Injil ati ohun ti A sokale fun won lati odo Oluwa won (iyen, al-Ƙur’an), won iba maa je lati oke won ati lati isale ese won. Ijo kan n be ninu won t’o duro deede, (amo) ohun ti opolopo ninu won n se nise buru

[67] Iwo Ojise, fi gbogbo ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa re jise. Ti o o ba si se bee, o o jise pe. Allahu yo si daabo bo o lodo awon eniyan. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo (lati se o ni aburu)

[68] So pe: “Eyin ahlul-kitab, e o ri kini kan se (ninu esin) titi e maa fi lo at-Taorah ati al-’Injil ati ohun ti A sokale fun yin lati odo Oluwa yin (iyen, al-Ƙur’an).” Ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa Re yoo kuku je ki opolopo won lekun ni igberaga ati aigbagbo ni. Nitori naa, ma se banuje nitori ijo alaigbagbo

[69] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo ati awon t’o di yehudi, - awon sobi’un ati awon kristieni, - enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si sise rere, ko nii si iberu fun won. Won ko si nii banuje

[70] A kuku gba adehun lowo awon omo ’Isro’il. A si ran awon Ojise kan si won. Igbakigba ti Ojise kan ba de ba won pelu ohun ti emi won ko fe, won pe igun kan ni opuro, won si n pa igun kan

[71] Won si lero pe ko nii si ifooro; won foju, won si diti (si ododo). Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Leyin naa, won foju, won tun diti (si ododo); opolopo ninu won (lo se bee). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

[72] Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu, Oun ni Mosih omo Moryam.” Mosih si so pe: "Eyin omo ’Isro’il, e josin fun Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin. Dajudaju enikeni ti o ba ba Allahu wa akegbe, Allahu ti se Ogba Idera ni eewo fun un. Ina si ni ibugbe re. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi

[73] Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Iketa (awon) meta.” Ko si si olohun kan ti ijosin to si afi Olohun, Okan soso. Ti won ko ba jawo nibi ohun ti won n wi, dajudaju iya eleta elero l’o maa je awon t’o di keferi ninu won

[74] Nitori naa, se won ko nii ronu piwada sodo Allahu, ki won si toro aforijin lodo Re? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[75] Ki ni Mosih bi ko se Ojise kan. Awon Ojise si ti lo siwaju re. Olododo si ni iya re. Awon mejeeji maa n je ounje. Wo bi A se n salaye awon ayah naa. Leyin naa, wo bi won se n seri won kuro nibi ododo

[76] So pe: “Se e n josin fun leyin Allahu ohun ti ko ni ikapa inira ati anfaani kan fun yin? Allahu, Oun si ni Olugbo, Onimo.”

[77] So pe: "Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ti ki i se (esin) ododo. E ma si se tele ife-inu ijo kan t’o ti sina siwaju (iyen, awon yehudi). Won si opolopo lona. Won si sina kuro ni oju ona taara

[78] A sebi le awon t’o sai gbagbo ninu awon omo ’Isro’il lori ahon (Anabi) Dawud ati ‘Isa omo Moryam. Iyen nitori pe, won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu-ala

[79] Won ki i ko iwa ibaje ti won n se nise laaarin ara won. Ohun ti won n se nise si buru

[80] O maa ri opolopo ninu won t’o n sore awon t’o sai gbagbo. Ohun ti emi won ti siwaju fun won si buru to bee ge ti Allahu fi binu si won. Olusegbere si ni won ninu Iya

[81] Ti o ba je pe won gbagbo ninu Allahu ati Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam), ati ohun ti A sokale fun un, won ko nii mu won ni ore ayo, sugbon opolopo ninu won ni obileje

[82] Dajudaju o maa ri i pe awon eniyan ti ota won le julo si awon t’o gbagbo ni ododo ni awon yehudi ati awon osebo. Dajudaju o si maa ri i pe awon eniyan t’o sunmo awon t’o gbagbo ni ododo julo ni ife ni awon t’o wi pe: “Dajudaju nasara ni awa.” Iyen nitori pe awon alufaa ati olufokansin n be laaarin won. Ati pe dajudaju won ko nii segberaga (si ododo)

[83] Nigba ti won ba gbo ohun ti A sokale fun Ojise naa, o maa ri eyinju won ti o maa damije nitori ohun ti won ti mo ninu ododo. Won a si so pe: "Oluwa wa, a gbagbo ni ododo, ko wa mo ara awon olujerii (ododo)

[84] Ki ni o maa di wa lowo ti a o fi nii gbagbo ninu Allahu ati ohun ti o de ba wa ninu ododo (iyen, al-Ƙur’an), ti a si n jerankan pe ki Oluwa fi wa sinu awon eni-ire

[85] Nitori naa, nitori ohun ti won so, Allahu san won ni esan pelu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni esan fun awon oluse-rere

[86] Awon t’o si sai gbagbo, ti won pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim

[87] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se so awon nnkan daadaa ti Allahu se ni eto fun yin di eewo. E si ma se tayo enu-ala. Dajudaju Allahu ko feran awon olutayo enu-ala

[88] E je nnkan eto t’o dara ninu ohun ti Allahu se ni arisiki fun yin. Ati pe e beru Allahu, Eni ti eyin gbagbo ninu Re

[89] Allahu ko nii fi ibura ti o bo lenu yin bi yin, sugbon O maa fi awon ibura ti e finnufindo mu wa bi yin. Nitori naa, itanran re ni bibo talika mewaa pelu ounje ti o wa ni iwontun-wonsi ti e n fi bo ara ile yin, tabi ki e raso fun won, tabi ki e tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Enikeni ti ko ba ri (eyi se), o maa gba aawe ojo meta. Iyen ni itanran ibura yin nigba ti e ba bura. E so ibura yin. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun yin, nitori ki e le dupe

[90] Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju oti, tete, awon orisa ati ise yiyewo, egbin ninu ise Esu ni. Nitori naa, e jinna si i nitori ki e le jere

[91] Ohun ti Esu n fe ni pe o maa da ota ati ikorira sile laaarin yin nibi oti ati tete. O si fe se yin lori kuro nibi iranti Allahu ati nibi irun kiki. Se eyin ko nii jawo (nibi ise Esu) ni

[92] E tele ti Allahu, e tele ti Ojise. Ki e si sora. Nitori naa, ti e ba gbunri, ki e mo pe ise-jije ponnbele lojuse awon Ojise Wa

[93] Ko si ibawi fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere nipa ohun ti won je (ninu ounje siwaju ofin) nigba ti won ba ti beru Allahu, ti won si gbagbo ni ododo, ti won tun sise rere, leyin naa, ti won beru Allahu, ti won si gbagbo ni ododo, leyin naa, ti won beru Allahu, ti won tun sise rere. Allahu si feran awon oluse-rere

[94] Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju Allahu yoo fi kini kan dan yin wo nibi eran-igbe ti owo yin ati oko yin ba (ninu aso hurumi) nitori ki Allahu le safi han eni t’o n paya Re ni ikoko. Enikeni ti o ba tayo enu-ala leyin iyen, iya eleta-elero n be fun un

[95] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se pa eran-igbe nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. Enikeni ti o ba si moomo pa a ninu yin, itanran re ni (pe o maa pa) iru ohun ti o pa ninu eran osin. Awon onideede meji ninu yin l’o si maa se idajo (osuwon) re (fun un. O je) eran itanran ti o maa mu de Kaaba. Tabi ki o fi bibo awon talika se itanran. Tabi aaro iyen ni aawe, nitori ki o le to bi oran re se lagbara to wo. Allahu ti moju kuro nibi ohun t’o re koja. Enikeni ti o ba tun pada (moomo dode ninu aso hurumi), Allahu yoo gbesan lara re re. Allahu si ni Alagbara, Olugbesan

[96] Won se odo dide ati jije ounje (okunbete) inu re ni eto fun yin. Nnkan igbadun ni fun eyin ati awon onirin-ajo. Won si se igbe dide ni eewo fun yin nigba ti e ba wa ninu aso hurumi. E beru Allahu, Eni ti won maa ko yin jo si odo Re

[97] Allahu se Kaaba, Ile Haram, ni aye aabo fun awon eniyan. (Nnkan aabo naa ni) awon osu owo, awon eran ore (ti won ko sami si lorun) ati (awon eran ore) ti won sami si lorun. Iyen ri bee ki e le mo pe dajudaju Allahu mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[98] E mo pe dajudaju Allahu le nibi iya. Ati pe dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[99] Ko si ojuse kan fun Ojise naa bi ko se ise-jije. Allahu si mo ohun ti e n safi han re ati ohun ti e n fi pamo

[100] So pe: “Ohun buruku ati ohun daadaa ko dogba, pupo ohun buruku ibaa jo o loju”. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye, nitori ki e le jere.”

[101] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se maa beere nipa awon nnkan sa. Ti A ba fi han yin, o maa ko ipalara ba yin. Ti e ba si beere nipa (awon nnkan t’o ye lati beere nipa esin) nigba ti A n so al-Ƙur’an kale lowo, A maa fi han yin. Allahu ti se amojukuro nipa re. Allahu ni Alaforijin, Alafarada

[102] Ijo kan kuku ti beere re siwaju yin. Leyin naa, won si di alaigbagbo nipase re

[103] Allahu ko fi eran bahirah, eran sa’ibah, eran wasilah ati eran ham lole. Sugbon awon t’o sai gbagbo n da adapa iro mo Allahu ni. Opolopo won ni ko se laakaye

[104] Nigba ti won ba so fun won pe: “E maa bo wa sibi ohun ti Allahu sokale. (E maa bo wa) si odo Ojise naa.” Won a wi pe: “Ohun ti a ba awon baba wa lori re ti to wa.” Se pelu bi o se je pe awon baba won ko nimo kan kan, ti won ko si mona

[105] Eyin ti e gbagbo ni ododo, emi ara yin dowo yin. Eni ti o ti sina ko le ko inira ba yin nigba ti e ba ti mona. Odo Allahu ni ibupadasi gbogbo yin patapata. Nigba naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

[106] Eyin ti e gbagbo ni ododo, (e wa) eri jije laaarin yin nigba ti (ipokaka) iku ba de ba eni kan ninu yin ti o fe so asoole. (E wa) onideede meji ninu yin. Tabi awon meji miiran yato si yin ti eyin ba wa lori irin-ajo ti ajalu iku ba fe sele si yin. E da awon mejeeji duro leyin irun, ki won fi Allahu bura, ti e ba seyemeji (si ododo won, ki won si so pe:) "A o nii ta ibura wa ni iye kan kan, koda ko je ebi. A o si nii fi eri jije ti Allahu (pa lase) pamo. (Bi bee ko) nigba naa, dajudaju awa wa ninu awon elese

[107] Ti won ba si ri i pe awon mejeeji da ese (nipa yiyi asoole pada), ki awon meji miiran ninu awon ti awon mejeeji akoko se abosi si (iyen, ebi oku) ropo won. Ki awon naa si fi Allahu bura pe: "Dajudaju eri jije tiwa je ododo ju eri jije ti awon mejeeji (akoko). A o si nii tayo enu-ala. (Bi bee ko) nigba naa, dajudaju a ti wa ninu awon alabosi

[108] Iyen sunmo julo lati mu eri jije wa ni oju-ponna re tabi lati (le la ninu) ipaya pe won yoo da ibura kan nu leyin ibura tiwon. E beru Allahu, ki e si gboran. Allahu ki i fi ona mo ijo obileje

[109] Ni ojo ti Allahu yoo ko awon Ojise jo, O si maa so pe: “Ki ni esi ti won fun yin?” Won a so pe: “Ko si imo kan fun wa (nipa re). Dajudaju Iwo, Iwo ni Onimo nipa awon ikoko.”

[110] (Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, ranti idera Mi lori re ati lori iya re, nigba ti Mo fi emi Mimo (molaika Jibril) ran o lowo, ti o si n ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba ti o dagba. (Ranti) nigba ti Mo fun o ni imo Tira, ijinle oye, at-Taorah ati al-’Injil. (Ranti) nigba ti o n mo nnkan lati inu amo bi irisi eye, ti o n fe ategun sinu re, ti o n di eye pelu iyonda Mi. O n wo afoju ati adete san pelu iyonda. (Ranti) nigba ti o n mu awon oku jade (ni alaaye lati inu saree) pelu iyonda Mi. (Ranti) nigba ti Mo ko awon omo ’Isro’il lowo ro, nigba ti o mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon t’o sai gbagbo ninu won si wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”

[111] (Ranti) nigba ti Mo fi mo awon omoleyin re ninu okan won pe ki won gbagbo ninu Emi ati Ojise Mi. Won so pe: “A gbagbo. Ki o si jerii pe dajudaju musulumi ni wa.”

[112] (Ranti) nigba ti awon omoleyin re so pe: “‘Isa omo Moryam, nje Oluwa re le so opon ounje kan kale lati sanmo?” O so pe: "E beru Allahu ti e ba je onigbagbo ododo

[113] Won so pe: “A fe je ninu re, a si fe ki okan wa bale, ki a si le mo pe o ti so ododo fun wa. A si maa wa ninu awon olujerii.”

[114] ‘Isa omo Moryam so pe: "Allahu, Oluwa wa, so opon ounje kan kale fun wa lati inu sanmo, ki o je odun fun eni akoko wa ati eni ikeyin wa.1 Ki o si je ami kan lati odo Re. Pese fun wa, Iwo si loore julo ninu awon olupese

[115] Allahu so pe: “Dajudaju Emi yoo so o kale fun yin. Sugbon enikeni ti o ba sai gbagbo leyin naa ninu yin, dajudaju Mo maa je e niya kan ti Mi o fi je eni kan ri ninu gbogbo eda.”

[116] (Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, se iwo l’o so fun awon eniyan pe: "E mu emi ati iya mi ni olohun meji ti e oo maa josin fun leyin Allahu?" O so pe: "Mimo ni fun O, ko to fun mi lati so ohun ti emi ko letoo (si lati so). Ti mo ba so bee, O kuku ti mo. O mo ohun ti n be ninu emi mi. Ng o si mo ohun ti n be ninu emi Re. Dajudaju Iwo ni Onimo nipa awon ikoko

[117] Emi ko so ohun kan fun won bi ko se ohun ti O pa mi lase re pe: "E josin fun Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin." Mo si je elerii lori won niwon igba ti mo n be laaarin won. Sugbon nigba ti O gba mi kuro lowo won, Iwo ni Oluso lori won. Iwo si ni Arinu-rode gbogbo nnkan

[118] Ti O ba je won niya, dajudaju eru Re ni won. Ti O ba si fori jin won, dajudaju Iwo, Iwo ni Alagbara, Ologbon

[119] Allahu so pe: “Eyi ni ojo ti ododo awon olododo yoo se won ni anfaani. Awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re n be fun won. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). Iyen ni erenje nla

[120] Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa ninu won. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

Ẹran ọ̀sìn

Surah 6

[1] Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O da awon sanmo ati ile. O tun da okunkun ati imole. Sibesibe awon t’o sai gbagbo n ba Oluwa won wa akegbe

[2] Oun ni Eni ti O da yin lati inu erupe amo. Leyin naa, O fi gbedeke igba kan si (isemi aye yin). Ati pe gbedeke akoko kan (tun wa fun aye) lodo Re. Leyin naa, e tun n seyemeji

[3] Oun ni Allahu ninu awon sanmo ati ninu ile. O mo ikoko yin ati gbangba yin. O si mo ohun ti e n se nise

[4] Ko si ami kan ti o maa de ba won ninu awon ami Oluwa won, afi ki won maa gbunri kuro nibe

[5] Won kuku pe ododo niro nigba ti o de ba won. Nitori naa, laipe awon iro ohun ti won maa n fi se yeye n bo wa ba won

[6] Se won ko ri i pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won? Awon ti A fun ni ipo lori ile, (iru) ipo ti A ko fun eyin. A si ro omi ojo pupo fun won lati sanmo. A si se awon odo ti n san si isale (ile) won. Leyin naa, A pa won re nitori ese won. A si da awon iran miiran leyin won

[7] Ti o ba je pe A so tira kan ti A ko sinu takada kale fun o, ki won si fi owo won gba a mu (bayii), dajudaju awon t’o sai gbagbo iba wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”

[8] Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so molaika kan kale fun un?” Ti o ba je pe A so molaika kan kale, oro iba ti yanju. Leyin naa, A o si nii lo won lara mo

[9] Ti o ba je pe A se e ni molaika ni, Awa iba se e ni okunrin. Ati pe Awa iba tun fi ohun ti won n daru mora won loju ru won loju

[10] Won kuku ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re! Nitori naa, ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi awon t’o n fi won se yeye po

[11] So pe: “E rin ori ile lo, leyin naa ki e wo bawo ni atubotan awon t’o n pe ododo niro se ri.”

[12] So pe: “Ti ta ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile?” So pe: “Ti Allahu ni.” O se aanu ni oran-anyan lera Re lori. Dajudaju O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ko si iyemeji ninu re. Awon t’o se emi won lofo (sinu aigbagbo), won ko nii gbagbo

[13] TiRe ni ohunkohun t’o n be ninu oru ati osan. Oun si ni Olugbo, Onimo

[14] So pe: “Se ki ng mu oluranlowo kan yato si Allahu, Eledaa awon sanmo ati ile? Oun si ni O n bo (eda), won ki i bo O.” So pe: “Dajudaju Won pa mi lase pe ki ng je eni akoko ti o maa se ’Islam (ni asiko temi).” Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo. ofin Re ati ilana Re. Eyi ni awon kan mo si “sise ife-Olohun”. Ewo ninu awon Anabi Olohun ati Ojise Re ni ko juwo-juse sile patapata fun ase Allahu ofin Re ati ilana Re? Ewo ninu won se ni ko se ife-Olohun? Ko si. Idi niyi ti gbogbo won fi je musulumi gege bi Allahu (subhanahu wa ta'ala) se fi rinle ninu surah al-Baƙorah; 2:128-141. ofin Re ati ilana Re. Amo ninu ijo re oun ni eni akoko ti o koko se bee

[15] So pe: “Dajudaju emi n paya iya Ojo Nla, ti mo ba fi le yapa Oluwa mi.”

[16] Enikeni ti A ba dari re kuro nibi (iya) ni Ojo yen, (Allahu) ti saanu re. Iyen si ni erenje ponnbele

[17] Ti Allahu ba fi inira kan kan o, ko si eni ti o le mu un kuro afi Oun naa. Ti O ba si mu oore kan ba o, Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[18] Oun si ni Olubori t’O wa loke awon eru Re. Oun ni Ologbon, Onimo-ikoko

[19] So pe: “Ki ni ohun ti o tobi julo ni eri?” So pe: “Allahu ni Elerii laaarin emi ati eyin.” O si fi imisi al-Ƙur’an yii ranse si mi, nitori ki ng le fi se ikilo fun eyin ati enikeni ti (al-Ƙur’an) ba de eti igbo re. Se dajudaju eyin n jerii pe awon olohun miiran tun wa pelu Allahu ni? So pe: “Emi ko nii jerii bee.” So pe: “Oun nikan ni Olohun Okan soso ti ijosin to si. Ati pe dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo (si Allahu).”

[20] Awon ti A fun ni Tira, won mo on gege bi won se mo awon omo won. Awon t’o se emi won lofo (sinu aigbagbo), won ko si nii gbagbo

[21] Ta l’o si sabosi ju eni ti o da adapa iro mo Allahu tabi (eni ti) o pe awon ayah Re niro? Dajudaju awon alabosi ko nii jere

[22] Ati pe (ranti) Ojo ti A oo ko gbogbo won jo patapata, leyin naa A oo so fun awon t’o ba (Allahu) wa akegbe pe: “Nibo ni awon orisa yin wa, awon ti e n so nipa won lai ni eri lowo pe won je akegbe Allahu?”

[23] Leyin naa, ifooro won (lori ibeere naa) ko je kini kan tayo pe won a wi pe: “A fi Allahu, Oluwa wa bura, awa ki i se osebo.”

[24] Wo bi won se paro mora won. Ohun ti won n da ni adapa iro si dofo mo won lowo

[25] Eni ti n gbo oro ni odo re n be ninu won. A si fi ebibo bo okan won ki won ma baa gbo agboye re. (A tun fi) edidi sinu eti won. Ti won ba ri gbogbo ami, won ko nii gba a gbo debi pe nigba ti won ba wa ba o, won yo si maa ba o jiyan; awon t’o sai gbagbo si maa wi pe: “Ki ni eyi bi ko se akosile alo awon eni akoko.”

[26] Awon ni won n ko (fun awon eniyan lati tele Anabi s.a.w.), awon naa si n takete si i. Won ko si ko iparun ba enikeni bi ko se emi ara won; won ko si fura

[27] Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti A ba da won duro sibi Ina, won si maa wi pe: “Yee! Ki won si da wa pada (sile aye), awa ko si nii pe awon ayah Oluwa wa niro (mo), a si maa wa ninu awon onigbagbo ododo.”

[28] Ko ri bee, ohun ti won n fi pamo siwaju ti han si won ni. Ti o ba je pe A ba da won pada (sile aye), won yoo kuku pada sibi ohun ti A ko fun won. Dajudaju opuro ma ni won

[29] Won wi pe: "Ki ni (o tun je isemi orun) bi ko se isemi wa nile aye; Won ko si nii gbe wa dide (ni orun)

[30] Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti won ba da won duro si odo Oluwa won, O si maa so pe: “Se eyi ki i se ododo bi?” Won a si wi pe: “Rara (ododo ni), Oluwa wa.” (Allahu) so pe: “Nitori naa, e to Iya wo nitori pe e maa n sai gbagbo.”

[31] Dajudaju awon t’o pe pipade Allahu (lorun) niro ti sofo debi pe nigba ti Akoko naa ba de ba won lojiji, won a wi pe: “A ka abamo lori ohun ti a fi jafira.” Won si maa ru ese won seyin won. Kiye si i, ohun ti won yoo ru lese si buru

[32] Isemi aye ko si je kini kan bi ko se ere ati iranu. Ogba Ikeyin si loore julo fun awon t’o n beru (Allahu). Se e o se laakaye ni

[33] A kuku ti mo pe ohun ti won n wi yoo ba o ninu je. Dajudaju won ko le pe o ni opuro, sugbon awon alabosi n tako awon ayah Allahu ni

[34] Won kuku ti pe awon Ojise kan lopuro siwaju re. Won si se suuru lori nnkan ti won fi pe won ni opuro. Won si fi inira kan won titi di igba ti aranse Wa fi de ba won. Ko si si alayiipada kan fun awon oro Allahu. Dajudaju iro awon Ojise ti de ba o

[35] Ti o ba si je pe gbigbunri won lagbara lara re, nigba naa ti o ba lagbara lati wa iho kan sinu (aja) ile, tabi akaba kan sinu sanmo (se bee) ki o le mu ami kan wa fun won. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, dajudaju iba ko won jo sinu imona (’Islam). Nitori naa, o o gbodo wa lara awon alaimokan

[36] Awon t’o n gboro ni awon t’o n jepe. Awon oku, Allahu yo si gbe won dide. Leyin naa, odo Re ni won yoo da won pada si

[37] Won tun wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Dajudaju Allahu lagbara lati so ami kan kale, sugbon opolopo won ni ko mo.”

[38] Ko si ohun abemi kan (t’o n rin) lori ile, tabi eye kan t’o n fo pelu apa re mejeeji bi ko se awon eda kan (bi) iru yin. A ko fi kini kan sile (lai sakosile re) sinu Tira (iyen, ummul-kitab). Leyin naa, odo Oluwa won ni won yoo ko won jo si

[39] Awon t’o pe awon ayah Wa niro, aditi ati ayaya t’o wa ninu awon okunkun ni won. Enikeni ti Allahu ba fe, O maa si i lona. Enikeni ti O ba si fe, O maa fi soju ona taara (’Islam)

[40] So pe: "E so fun mi, ti iya Allahu ba de ba yin tabi ti Akoko naa ba de ba yin, se nnkan miiran leyin Allahu ni eyin maa pe, ti e ba je olododo

[41] Rara, Oun (nikan) l’e n pe. O si maa mu (inira) ti e n pe E si kuro (fun yin), ti O ba fe. Eyin yo si gbagbe ohun ti e n fi sebo si I

[42] Dajudaju A ti ranse si awon ijo kan siwaju re. A si fi iponju ati ailera gba won mu nitori ki won le rawo rase (si Allahu)

[43] Won ko se rawo rase (si Wa) nigba ti iya Wa de ba won! Sugbon okan won ti le koko. Esu si se ohun ti won n se nise ni oso fun won

[44] Nitori naa, nigba ti won gbagbe ohun ti A fi se iranti fun won, A si awon ona gbogbo nnkan sile fun won, titi di igba ti won yo ayoporo si ohun ti A fun won (ninu oore aye.), A si mu won lojiji. Won si di olusoretinu

[45] Nitori naa, A pa ijo t’o sabosi run patapata. Gbogbo ope si n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

[46] So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba gba igboro yin ati iriran yin, ti O si di okan yin pa, olohun wo leyin Allahu ni o maa mu un wa fun yin? Wo bi A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona. Leyin naa, won si n gbunri

[47] So pe: “E so fun mi, ti iya Allahu ba de ba yin ni ojiji tabi ni ojukoju, se won maa pa eni kan run bi ko se ijo alabosi!”

[48] A ko ran awon Ojise naa nise bi ko se pe (ki won je) oniroo idunnu ati olukilo. Nitori naa, enikeni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se atunse (ise re), ko nii si iberu fun won, won ko si nii banuje

[49] Awon t’o si pe awon ayah Wa niro, owo iya yoo te won nitori pe won maa n sebaje

[50] So pe: “Emi ko so fun yin pe awon ile-owo Allahu wa lodo mi, emi ko si nimo ikoko. Emi ko si so fun yin pe molaika kan ni mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi.” So pe: "Nje afoju ati oluriran dogba bi? Se e o ronu jinle ni

[51] Fi (al-Ƙur’an) se ikilo fun awon t’o n paya pe Won maa ko awon jo si odo Oluwa won, ko si nii si alaabo tabi olusipe kan fun won leyin Re. (Kilo fun won) ki won le beru (Allahu)

[52] Ma se le awon t’o n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale danu; won n fe Oju rere Re ni. Isiro-ise won ko si ni orun re ni ona kan kan. Ko si si isiro-ise tire naa ni orun won ni ona kan kan. Ti o ba le won danu, o si maa wa ninu awon alabosi

[53] Bayen ni A se fi apa kan won se adanwo fun apa kan nitori ki (awon alaigbagbo) le wi pe: “Se awon (musulumi alaini) wonyi naa ni Allahu se idera (imona) fun laaarin wa!?” Se Allahu ko l’O nimo julo nipa awon oludupe ni

[54] Nigba ti awon t’o gba awon ayah Wa gbo ba wa ba o, so (fun won) pe: "Ki alaafia maa ba yin. Oluwa yin se aanu ni oran-anyan lera Re lori pe, dajudaju enikeni ninu yin ti o ba se ise aburu pelu aimokan, leyin naa, ti o ronu piwada leyin re, ti o si se atunse, dajudaju Oun ni Alaforijin, Asake-orun

[55] Bayen ni A se n salaye awon ayah nitori ki ona awon elese le foju han kedere

[56] So pe: “Dajudaju Won ko fun mi lati josin fun awon ti e n pe leyin Allahu.” So pe: “Emi ko nii tele ife-inu yin. Bi bee ko nigba naa, mo ti sina (ti mo ba tele ife-inu yin). Emi ko si si ninu awon olumona.”

[57] So pe: “Dajudaju mo wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, eyin si pe e niro. Ko si ohun ti e n wa pelu ikanju ni odo mi. Ko si idajo naa (fun enikeni) ayafi fun Allahu, Eni ti n so (idajo) ododo. O si loore julo ninu awon oludajo.”

[58] So pe: “Ti o ba je pe dajudaju ohun ti e n wa pelu ikanju n be ni odo mi ni, Won iba ti se idajo oro naa laaarin emi ati eyin. Allahu si nimo julo nipa awon alabosi.”

[59] Odo Re si ni awon kokoro ikoko wa. Ko si eni t’o nimo re afi Oun. O nimo ohun ti n be ninu ile ati odo. Ewe kan ko si nii ja bo afi ki O nimo re. Ko si si koro eso kan ninu okunkun (inu) ile, ko si ohun tutu tabi gbigbe kan afi ki o wa ninu akosile t’o yanju

[60] Oun ni Eni t’O n kun yin ni oorun ni ale. O si nimo nipa ohun ti e se nise ni osan. Leyin naa, O n gbe yin dide (fun ije-imu) ni (osan) nitori ki won le pari gbedeke akoko kan. Leyin naa, odo Re ni ibupadasi yin. Leyin naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

[61] Oun ni Olubori t’O wa loke awon eru Re. O si n ran awon eso kan si yin titi di igba ti iku yoo fi de ba eni kookan yin. Awon Ojise wa yo si gba emi re, won ko si nii jafira

[62] Leyin naa, won yoo da won pada si odo Allahu, Oluwa won, Ododo. Kiye si i, tiRe ni idajo. Oun si yara julo ninu awon olusiro

[63] So pe: “Ta ni eni t’o n gba yin la ninu okunkun ile ati ibudo, Eni ti e n pe pelu iraworase ati ni ikoko pe: "Dajudaju ti O ba gba wa la ninu eyi, dajudaju awa yoo wa ninu awon oludupe (fun Un)

[64] So pe: “Allahu l’O n gba yin la ninu re ati ninu gbogbo ibanuje. Leyin naa, e tun n sebo.”

[65] So pe: “O lagbara lati fi iya ranse si yin lati oke yin tabi lati isale ese yin, tabi ki O da yin po mo oniruuru ijo, nitori ki O le mu apa kan yin finira kan apa kan. Wo bi A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona nitori ki won le gbo agboye.”

[66] Awon eniyan re pe al-Ƙur’an niro! (Amo) ododo ni. So pe: “Emi ki i se oluso lori yin.”

[67] Gbogbo asotele l’o ni akoko (isele). Laipe e maa mo

[68] Nigba ti o ba ri awon t’o n so isokuso nipa awon ayah Wa, nigba naa seri kuro ni odo won titi won yoo fi bo sinu oro miiran. Ti Esu ba n mu o gbagbe (tele), ni bayii leyin iranti ma se jokoo ti ijo alabosi

[69] Kini kan ninu isiro-ise won ko si lorun awon t’o n beru (Allahu), sugbon isiti ni nitori ki won le sora (fun Ina)

[70] Pa awon t’o so esin won di ere sise ati iranu ti. Isemi aye si tan won je. Fi (al-Ƙur’an) se isiti nitori ki won ma baa fa emi kale sinu iparun nipase ohun ti o se nise (aburu). Ko si si alaabo tabi olusipe kan fun un leyin Allahu. Ti o ba si fi gbogbo aaro serapada, A o nii gba a lowo re. Awon wonyen ni awon ti won fa kale fun iparun nipase ohun ti won se nise. Ohun mimu gbigbona ati iya eleta elero n be fun won nitori pe won maa n sai gbagbo

[71] So pe: “Se a oo maa pe leyin Allahu, ohun ti ko le se wa ni anfaani, ti ko si le ko inira ba wa; (se) ki won tun da wa pada si ese-aaro wa leyin igba ti Allahu ti fi ona mo wa (ki a le da) bi eni ti Esu mu tele ife-inu re lori ile aye, ti idaamu de ba? O (si) ni awon ore kan ti won n pe e sibi imona (pe), “Maa bo ni odo wa.” So pe: “Dajudaju imona ti Allahu (’Islam), ohun ni imona. Won si pa wa lase pe ki a gba esin ’Islam nitori ti Oluwa gbogbo eda.”

[72] Ati pe ki e kirun, ki e si beru Allahu. Oun ni Eni ti won yoo ko yin jo si odo Re

[73] Oun si ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. Ati pe (ranti) ojo ti (Allahu maa yi ile ati sanmo pada si nnkan miiran), O si maa so pe: "Je bee." O si maa je bee. Ododo ni oro Re. TiRe si ni ijoba ni ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. Onimo-ikoko ati gbangba ni. Oun si ni Ologbon, Alamotan

[74] (Ranti) nigba ti ’Ibrohim so fun baba re, Azar, (pe): “Se o maa so awon ere orisa di olohun ni? Dajudaju emi ri iwo ati awon eniyan re ninu isina ponnbele.”

[75] Bayen ni won se fi (awon ami) ijoba Allahu ti n be ninu awon sanmo ati ile han (Anabi) ’Ibrohim nitori ki o le wa ninu awon alamodaju

[76] Nigba ti okunkun ale bo o mole, o ri irawo kan, o so pe: “Eyi ni oluwa mi.” Nigba ti o wo, o so pe: “Emi ko nifee si awon (oluwa) t’o n wookun.”

[77] Nigba ti o ri osupa t’o yo, o so pe: “Eyi ni oluwa mi.” Nigba ti o wo, o so pe: “Dajudaju ti Oluwa mi ko ba to mi sona, dajudaju mo maa wa ninu awon olusina eniyan.”

[78] Nigba ti o ri oorun t’o yo, o so pe: “Eyi ni oluwa mi; eyi tobi julo.” Nigba t’o wo, o so pe: “Eyin eniyan mi, dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo (si Allahu)

[79] Dajudaju emi doju mi ko Eni ti O pile iseda awon sanmo ati ile, (mo) duro deede (sinu ’Islam fun Un). Emi ko si si ninu awon osebo.”

[80] Awon eniyan re si ja a niyan. O so pe: "Se eyin yoo ja mi niyan nipa Allahu, O si ti fi ona mo mi? Emi ko si paya (awon orisa) ti e so di akegbe fun Un, afi bi Allahu ba fe kini kan (pe ko sele). Oluwa mi fi imo gbooro ju gbogbo nnkan. Nitori naa, se e o nii lo iranti ni

[81] Bawo ni emi yoo se paya (awon orisa) ti e so di akegbe fun Allahu, ti eyin ko si paya pe e n ba Allahu wa akegbe pelu ohun ti ko so eri kan kale fun yin lori re? Ewo ninu iko mejeeji l’o letoo julo si ifokanbale ti e ba nimo

[82] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won ko si da igbagbo won po mo abosi (iborisa), awon wonyen ni ifokanbale n be fun. Awon si ni olumona

[83] Iyen ni awijare Wa ti A fun (Anabi) ’Ibrohim lori awon eniyan re. A n se agbega ipo fun eni ti A ba fe. Dajudaju Oluwa re ni Ologbon, Onimo

[84] Ati pe A ta a lore (Anabi) ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (ti o je omo ’Ishaƙ). Ikookan won ni A fi mona. A si fi (Anabi) Nuh mona siwaju. Ati pe ninu aromodomo (Anabi ’Ibrohim ti A fi mona ni awon Anabi) Dawud, Sulaemon, ’Ayyub, Yusuf, Musa ati Harun. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

[85] Ati (Anabi) Zakariyya, Yahya, ‘Isa ati ’Ilyas; gbogbo won wa ninu awon eni rere

[86] Ati ’Ismo‘il, al-Yasa‘, Yunus ati Lut; ikookan won ni A soore ajulo fun lori awon eda (asiko won)

[87] Ati pe ninu awon baba won, aromodomo won ati awon arakunrin won, A sa won lesa. A si fi won mona taara (’Islam)

[88] Iyen ni imona Allahu. O si n fi to eni ti O ba fe si ona ninu awon eru Re. Ti won ba fi le sebo ni, dajudaju ohun ti won n se nise (rere) iba baje mo won lowo

[89] Awon wonyen ni awon ti A fun ni Tira, ijinle oye (iyen, sunnah) ati (ipo) Anabi. Nitori naa, ti awon wonyi ba sai gbagbo ninu re, dajudaju A ti gbe e le awon eniyan kan lowo, ti won ko nii sai gbagbo ninu re

[90] Awon wonyen ni awon ti Allahu to si ona. Nitori naa, ona won ni ki o tele. So pe: “Emi ko bi yin ni owo-oya kan lori re. Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda.”

[91] Won ko fun Allahu ni iyi ti o to si I, nigba ti won wi pe: “Allahu ko so nnkan kan kale fun abara kan.” So pe: "Ta ni O so tira ti (Anabi) Musa mu wa kale, (eyi t’o je) imole ati imona fun awon eniyan, eyi ti e sakosile re sinu iwe ajako, ti e n se afihan re, ti e si n fi opolopo re pamo, A si fi ohun ti e o mo mo yin, eyin ati awon baba yin?" So pe: "Allahu ni." Leyin naa, fi won sile sinu isokuso won, ki won maa sere

[92] Eyi (al-Ƙur’an) tun ni Tira ibukun ti A sokale; o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ati pe nitori ki o le se ikilo fun ’Ummul-Ƙuro (iyen, ara ilu Mokkah) ati enikeni ti o ba wa ni ayika re (iyen, ara ilu yooku). Awon t’o gbagbo ninu Ojo Ikeyin, won gbagbo ninu re. Awon si ni won n so irun won

[93] Ta l’o sabosi ju eni ti o da adapa iro mo Allahu tabi eni ti o wi pe won fi imisi ranse si mi - A o si fi kini kan ranse si i - ati eni ti o wi pe "Emi naa yoo so iru ohun ti Allahu sokale kale."? Ti o ba je pe iwo ri i nigba ti awon alabosi ba wa ninu ipokaka iku, ti awon molaika nawo won (si won pe) “E mu emi yin jade wa. Lonii ni Won yoo san yin ni esan abuku iya nitori ohun ti e maa n so nipa Allahu ni aito. E si maa n se igberaga si awon ayah Re.”

[94] Dajudaju e ti wa ba wa ni ikookan gege bi A se seda yin nigba akoko. E si ti fi ohun ti A fun yin sile si eyin yin. A o ma ri awon olusipe yin pelu yin, awon ti e so lai ni eri pe dajudaju laaarin yin awon ni akegbe (fun Allahu). Dajudaju asepo aarin yin ti ja patapata. Ati pe ohun ti e n so nipa won (lai ni eri lowo lori isipe yin) ti dofo mo yin lowo

[95] Dajudaju Allahu l’O n mu koro eso irugbin ati koro eso dabinu hu jade. O n mu alaaye jade lati ara oku. O si n mu oku jade lati ara alaaye. Iyen ni Allahu. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo

[96] O n mu ojumo mo. O se oru ni isinmi. (O n mu) oorun ati osupa (rin) fun isiro (ojo aye). Iyen ni eto Alagbara, Onimo

[97] Oun ni Eni ti O fi awon irawo se (imole) fun yin ki e le fi riran ninu okunkun ile ati ibudo. A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o nimo

[98] Oun ni Eni ti O seda yin lati ara emi eyo kan. Nitori naa, ibugbe (nile aye) ati ibupadasi (ni orun wa fun yin). A kuku ti salaye awon ayah fun awon eniyan t’o ni agboye

[99] Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. A fi mu gbogbo nnkan ogbin jade. A tun mu eweko t’o n dan logbologbo jade lati inu re. A tun n mu siri eso jade ninu re. (A si n mu jade) lati ara igi dabinu, lati ara eso akoyo re, eso t’o sujo mora won t’o ro dede wale. (A n se) awon ogba oko eso ajara, eso zaetun ati eso rummon (ni awon eso t’o) jora ati (awon eyi ti) ko jora. E wo eso re nigba ti o ba so ati (nigba ti o ba) pon. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo

[100] Won si fi awon alujannu se akegbe fun Allahu. Oun si l’O sedaa won! Won tun paro mo On (pe) O bi omokunrin ati omobinrin, lai nimo kan (nipa Re). Mimo ni fun Un. O si ga tayo ohun ti won n fi royin (Re)

[101] Olupileda awon sanmo ati ile ni. Bawo ni O se ni omo nigba ti ko ni aya. O da gbogbo nnkan. Oun si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[102] Iyen ni Allahu, Oluwa yin; ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Eledaa gbogbo nnkan. Nitori naa, e josin fun Un. Oun si ni Oluso lori gbogbo nnkan

[103] Awon oju (eda) ko le ka Allahu. Oun si ka awon oju. Oun si ni Alaaanu, Alamotan

[104] Awon eri t’o daju kuku ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, enikeni t’o ba riran, fun emi ara re ni. Enikeni t’o ba si foju, fun emi ara re ni. Emi ki i se oluso lori yin

[105] Bayen ni A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona nitori ki won le wi pe: "O kekoo (re lodo awon eniyan ni." Dipo ki won wi pe: "Won so o kale fun o ni." ati nitori ki A le se alaye re fun awon eniyan t’o nimo)

[106] Tele ohun ti won fi ran o ni imisi lati odo Oluwa re. Ko si eni ti ijosin to si afi Oun. Ki o si seri kuro ni odo awon osebo

[107] Ti o ba je pe Allahu ba fe (imona fun won), won iba ti sebo. A o si fi o se oluso lori won. Ati pe iwo ko ni alamojuuto won

[108] E ma se bu awon (orisa) ti won n pe leyin Allahu, ki awon (aborisa) ma baa bu Allahu ni ti abosi ati ainimo. Bayen ni A ti se ise ijo kookan ni oso fun won. Leyin naa, odo Oluwa won ni ibupadasi won. Nitori naa, O maa fun won ni iro ohun ti won maa n se nise

[109] Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe, dajudaju ti ami (iyanu) kan ba de ba awon, awon gbodo gba a gbo. So pe: "Odo Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa." Ki si ni o maa mu yin fura mo pe dajudaju nigba ti o ba de (ba won) won maa gba a gbo

[110] A maa yi okan won ati oju won sodi ni; (won ko nii gba a gbo) gege bi won ko se gbagbo ninu (eyi t’o siwaju ninu awon ami iyanu) nigba akoko. A o si fi won sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida

[111] Dajudaju ti A ba so awon molaika kale fun won, ti awon oku n ba won soro, ti A tun ko gbogbo nnkan jo siwaju won, won ko nii gbagbo afi ti Allahu ba fe. Sugbon opolopo won ni alaimokan

[112] Bayen ni A ti se awon esu eniyan ati esu alujannu ni ota fun Anabi kookan; apa kan won n fi odu iro ranse si apa kan ni ti etan. Ti o ba je pe Oluwa re ba fe (lati to won sona ni) won iba ti se bee. Nitori naa, fi won sile tohun ti adapa iro ti won n da

[113] Ki awon okan ti won ko gba Ojo Ikeyin gbo maa teti beleje si (odu iro Esu), ki won maa yonu si i, ki won si maa da ohun ti won n da lese n so

[114] Se nnkan miiran ni ki ng wa ni oludajo leyin Allahu ni? Oun si ni Eni ti O so Tira kale fun yin ti won fi salaye idajo. Awon ti A si fun ni tira mo pe, dajudaju won so o kale pelu ododo lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji

[115] Oro Oluwa re pe ni ododo ati ni deede. Ko si alayiipada kan fun awon oro Re. Oun si ni Olugbo, Onimo

[116] Ti o ba tele opolopo awon ti n be lori ile, won maa si o lona kuro loju ona (esin) Allahu. Won ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni won (n se) bi ko se pe won n paro

[117] Dajudaju Oluwa re, Oun l’O nimo julo nipa eni t’o sina loju ona (esin) Re. Ati pe, Oun si l’O nimo julo nipa awon olumona

[118] Nitori naa, e je ninu ohun ti won ba fi oruko Allahu pa, ti e ba gbagbo ninu awon ayah Re

[119] Ki ni o maa ko fun yin lati je ninu ohun ti won fi oruko Allahu pa! O kuku ti salaye fun yin ohun ti O se ni eewo fun yin ayafi eyi ti inira (ebi) ba ti yin debe. Dajudaju opolopo ni won n fi ife-inu won pelu ainimo (won) si awon eniyan lona. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa awon olutayo enu-ala

[120] E fi eyi t’o han ninu ese ati eyi t’o pamo ninu re sile. Dajudaju awon t’o n se ise ese, A oo san won ni esan ohun ti won n da lese

[121] Eyin ko si gbodo je ninu ohun ti won ko fi oruko Allahu pa. Dajudaju ibaje ni. Ati pe dajudaju awon esu, won yoo maa fi irande odu iro ranse si awon eni won, nitori ki won le tako yin. Ti e ba fi le tele won, dajudaju e ti di osebo

[122] Nje eni ti (afiwe re) je oku (iyen, alaigbagbo), ti A so di alaaye (nipa pe o gba ’Islam), ti A si fun un ni imole (iyen, imo esin), ti o si n lo o laaarin awon eniyan, (nje) o da bi eni ti afiwe tire je (eni ti) n be ninu awon okunkun (aigbagbo), ti ko si jade kuro ninu re? Bayen ni won ti se ni oso fun awon alaigbagbo ohun ti won n se nise

[123] Bayen ni A se so awon agba kan di odaran ilu ninu ilu kookan, nitori ki won le maa dete nibe. Won ko si dete si enikeni bi ko se si ara won, won ko si fura

[124] Nigba ti ayah kan ba si de ba won, won a wi pe: “Awa ko nii gba a gbo titi di igba ti won ba to fun awa naa ni iru ohun ti won fun awon Ojise Allahu.” Allahu nimo julo nipa ibi ti O n fi ise-riran Re si. Laipe iyepere ati iya lile lati odo Allahu yoo de ba awon t’o dese nitori ohun ti won n da lete

[125] Enikeni ti Allahu ba fe fona mo, O maa si igba-aya re paya fun ’Islam. Enikeni ti O ba si fe si lona, O maa fun igba-aya re pa gadigadi bi eni pe o n gunke lo sinu sanmo. Bayen ni Allahu se de wahala asan si awon ti ko gbagbo

[126] Eyi ni oju ona Oluwa re (t’o je) ona taara. A kuku ti salaye awon ayah fun ijo t’o n lo iranti

[127] Ile alaafia n be fun won ni odo Oluwa won. Oun si ni Alatileyin won nipa ohun ti won n se nise

[128] (Ranti) Ojo ti (Allahu) yoo ko gbogbo won jo patapata, (O maa so pe): “Eyin awujo alujannu, dajudaju e ti ko opolopo eniyan sonu.” Awon ore won ninu awon eniyan yoo wi pe: “Oluwa wa, apa kan wa gbadun apa kan ni. A si ti lo asiko wa ti O bu fun wa (lati lo).” (Allahu) so pe: “Ina ni ibugbe yin; olusegbere ni yin ninu re afi ohun ti Allahu ba fe . Dajudaju Oluwa re ni Ologbon, Onimo

[129] Bayen ni A se fi apa kan awon alabosi sore apa kan (won) nitori ohun ti won n se nise

[130] Eyin awujo alujannu ati eniyan, se awon Ojise kan laaarin yin ko wa ba yin, ti won n ke awon ayah Mi fun yin, ti won si n fi ipade yin Oni yii sekilo fun yin? Won wi pe: “A jerii lera wa lori (pe won wa).” Isemi aye tan won je. Won si jerii lera won lori pe dajudaju awon je alaigbagbo

[131] Iyen nitori pe Oluwa re ko nii pa awon ilu run nipase abosi (owo won), lasiko ti awon ara ilu naa je alaimo (titi Ojise yoo fi de ba won)

[132] Awon ipo (ike ati ipo iya) n be fun enikookan nipase ohun ti won ba se nise. Oluwa re ki i se onigbagbe nipa nnkan ti won n se nise

[133] Oluwa re ni Oloro, Alaaanu. Ti O ba fe, O maa ko yin kuro (lori ile). O si maa fi ohun ti O ba fe ropo (yin) leyin (iparun) yin gege bi O ti se mu yin jade leyin (iparun) aromodomo awon ijo miiran

[134] Dajudaju ohun ti A n se ni adehun fun yin, o kuku n bo wa sele; eyin ko si nii mori bo

[135] So pe: “Eyin eniyan mi, e duro sori ona yin, dajudaju emi naa yoo duro (sori ona mi), laipe e maa mo eni ti Ogba (Idera) yoo je ikangun tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”

[136] Won si fi ipin kan fun Allahu ninu ohun ti O da ninu nnkan oko ati eran-osin; won wi pe: "Eyi ni ti Allahu – pelu oro won lai ni eri lowo, - eyi si ni ti awon orisa wa." Nitori naa, ohun ti o ba je ti awon orisa ko nii dapo mo ti Allahu. Ohun ti o ba si je ti Allahu, o n dapo mo ti awon orisa won; ohun ti won n da lejo buru

[137] Bayen ni awon orisa won se pipa awon omo won ni oso fun opolopo ninu awon osebo nitori ki won le pa won run ati nitori ki won le d’oju esin won ru mo won lowo. Ti o ba je pe Allahu ba fe, won iba ti se (bee). Nitori naa, fi won sile tohun ti ohun ti won n da ni adapa iro

[138] Won tun wi pe: "Eewo ni awon eran-osin ati nnkan oko wonyi. Eni kan ko gbodo je e afi eni ti a ba fe, pelu oro won lai ni eri lowo." - Awon eran-osin kan tun n be ti won se eyin won ni eewo (fun gigun ati eru riru), awon eran kan tun n be ti won ki i fi oruko Allahu pa. (Won fi awon nnkan wonyi) da adapa iro mo Allahu ni. O si maa san won ni esan ohun ti won n da ni adapa iro

[139] Won tun wi pe: "Ohun ti n be ninu ikun awon eran-osin wonyi je ti awon okunrin wa nikan soso, o si je eewo fun awon obinrin wa." Ti o ba si je oku omo-eran, akegbe si ni won ninu (ipin) re. (Allahu) yoo san won ni esan iro (enu) won. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo

[140] Awon t’o fi ago ati aimo pa awon omo won kuku ti sofo; won tun se ohun ti Allahu pa lese fun won ni eewo, ni ti dida adapa iro mo Allahu. Won kuku ti sina, won ko si je olumona

[141] (Allahu) Oun ni Eni ti O seda awon nnkan ogba oko eyi ti e n fowo ara yin gbin ati eyi t’o n lale hu ati dabinu ati irugbin ti (adun) jije re yato sira won, ati eso zaetun ati eso rummon t’o jora won ati eyi ti ko jora won. E je ninu eso re nigba ti o ba so, ki e si yo Zakah re ni ojo ikore re. Ki e si ma yapa. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon apa

[142] O si n be ninu awon eran-osin, eyi t’o le ru eru ati eyi ti ko le ru eru. E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin. Ki e si ma se tele awon oju-ese Esu; dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

[143] (Allahu da eran) mejo ni tako-tabo; meji ninu agutan (tako-tabo), meji ninu ewure (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. E fun mi ni iro pelu imo ti e ba je olododo

[144] Meji ninu rakunmi (tako-tabo) ati meji ninu maalu (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. Tabi se eyin wa nibe nigba ti Allahu pa yin lase eyi ni?" Nitori naa, ta ni o se abosi t’o tun tayo eni t’o da adapa iro mo Allahu lati le si awon eniyan lona pelu ainimo. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

[145] So pe: "Emi ko ri ninu ohun ti Won fi ranse si mi ti Won se jije re ni eewo fun eni ti o n je e afi ohun ti o ba je eran okunbete tabi eje sisan,1 tabi eran elede nitori pe dajudaju egbin ni, tabi eran iyapa (ase Allahu) ti won pa pelu oruko t’o yato si Allahu. Nitori naa, enikeni ti inira (ebi) ba mu je e, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, dajudaju Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun

[146] A se e ni eewo fun awon t’o di yehudi gbogbo eran eleeekanna (tabi onipatako t’o supo mora won). Ninu eran maalu ati agutan, A tun se ora awon mejeeji ni eewo fun won afi eyi ti o ba le mo eyin won tabi ifun tabi eyi ti o ba ropo mo eegun. Iyen ni A fi san won ni esan nitori abosi owo won. Dajudaju Awa si ni Olododo

[147] Ti won ba si pe o ni opuro, so nigba naa pe: "Oluwa yin ni Onikee to gbooro. Ko si si eni t’o le gbe iya Re kuro lori ijo elese

[148] Awon t’o n sebo yoo wi pe: "Ti ko ba je pe Allahu ba fe ni awa ati awon baba wa iba ti sebo, ati pe awa iba ti se nnkan kan leewo." Bayen ni awon t’o siwaju won se pe oro Allahu niro titi won fi to iya Wa wo. So pe: "Nje imo kan n be ni odo yin, ki e mu un jade fun wa?" Eyin ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni e n so bi ko se pe e n paro

[149] So pe: "Ti Allahu ni eri t’o pe perepere." Nitori naa, ti O ba fe ni, iba fi gbogbo yin mona patapata

[150] So pe: "E mu awon elerii yin jade, awon t’o maa jerii pe dajudaju Allahu l’o se eyi leewo." Ti won ba jerii (siro), iwo ma se ba won jerii (si i). Ma si se tele ife-inu awon t’o pe awon ayah Wa niro ati awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo. Awon si ni won n ba Oluwa won wa akegbe

[151] So pe: "E wa ki ng ka ohun ti Oluwa yin se ni eewo fun yin; pe ki e ma se fi nnkan kan sebo si I, (ki e si se) daadaa si awon obi (yin) mejeeji, ki e si ma se pa awon omo yin nitori (iberu) osi, – Awa ni A n pese fun eyin ati awon – ki e si ma se sunmo awon iwa ibaje – eyi t’o han ninu re ati eyi t’o pamo, - ati pe ki e si ma se pa emi (eniyan) ti Allahu se ni eewo ayafi ni ona eto. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le se laakaye

[152] E ma se sunmo dukia omo orukan ayafi ni ona t’o dara julo titi o fi maa dagba. E won kongo ati osuwon pe daadaa. A ko labo emi kan lorun ayafi iwon agbara re. Ti e ba soro, e se deede, ibaa je ibatan. Ki e si pe adehun Allahu. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le lo iranti

[153] Ati pe dajudaju eyi ni ona Mi (ti o je ona) taara. Nitori naa, e tele e. E ma se tele awon oju ona (miiran) nitori ki o ma baa mu yin yapa oju ona (esin) Re. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le beru (Re)

[154] Leyin naa, A fun (Anabi) Musa ni Tira ni pipe perepere fun eni ti o maa se daadaa. (O je) alaye fun gbogbo nnkan. (O tun je) imona ati ike nitori ki won le ni igbagbo ninu ipade Oluwa won

[155] Eyi ni Tira ibukun ti A sokale. Nitori naa, e tele e. Ki e si beru (Allahu) nitori ki A le ke yin

[156] Nitori ki e ma se wi pe: “Owo ijo meji ti o siwaju wa ni Won so Tira kale fun. A si je alainimo nipa eko won.”

[157] Tabi ki e ma baa wi pe: “Dajudaju Won iba so Tira kale fun wa ni, awa iba mona ju won lo.” Eri t’o yanju, imona ati ike kuku ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ta ni o se abosi ju eni t’o pe awon ayah Allahu niro, t’o tun gbunri kuro nibe? A maa san awon t’o n gbunri kuro nibi awon ayah Wa ni (esan) iya buruku nitori pe won n gbunri (kuro nibe)

[158] Se won n reti nnkan (miiran) bi ko se pe ki awon molaika wa ba won tabi ki Oluwa re wa ba won tabi ki apa kan awon ami Oluwa re wa ba won? Ni ojo ti apa kan awon ami Oluwa re ba wa ba won, igbagbo (ti) emi kan ko ti i gbagbo teletele tabi ise rere (ti) emi kan ko ti i fi igbagbo re se (teletele) ko nii se e ni anfaani (lasiko naa). So pe: “E maa reti, dajudaju Awa naa n reti (Ojo naa)

[159] Dajudaju awon t’o ya esin won si otooto, ti won si di ijo-ijo, iwo ko ni nnkan kan se po pelu won. Oro won si n be ni odo Allahu. Leyin naa, O maa fun won ni iro ohun ti won n se nise

[160] Enikeni t’o ba mu ise daadaa wa, (esan) mewaa iru re l’o maa wa fun un. Enikeni t’o ba si mu ise aburu wa, A o nii san an ni esan ayafi iru re. A o si nii sabosi si won

[161] So pe: “Dajudaju Oluwa mi ti fi ona taara (’Islam) mo mi, esin t’o fese rinle, esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-esin, ko si si ninu awon osebo.”

[162] So pe: "Dajudaju irun mi, eran (pipa) mi, isemi aye mi ati iku mi n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

[163] Ko si akegbe fun Un. Iyen ni Won pa lase fun mi. Emi si ni eni-akoko awon musulumi (ni asiko temi)

[164] So pe: "Se emi yoo tun wa oluwa kan yato si Allahu ni, nigba ti o je pe Oun ni Oluwa gbogbo nnkan. Emi kan ko si nii se ise kan afi fun emi ara re. Eleru-ese kan ko si nii ru ese elomiiran. Leyin naa, odo Oluwa yin ni ibupadasi yin. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n yapa enu si.”

[165] Oun ni Eni ti O se yin ni arole lori ile. O si fi awon ipo gbe yin ga ju ara yin lo nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin. Dajudaju Oluwa re ni Oluyara nibi iya. Dajudaju Oun si ni Alaforijin, Asake-orun

Àwọn ibi gíga

Surah 7

[1] ’Alif lam mim sod

[2] Tira kan ti A sokale fun o (niyi). Nitori naa, ma se je ki iyemeji wa ninu okan re nipa re lati fi se ikilo ati iranti fun awon onigbagbo ododo

[3] E tele ohun ti won sokale fun yin lati odo Oluwa yin. Ki e si ma se tele awon wolii (esu) leyin Re. Die l’e n lo ninu iranti

[4] Meloo meloo ninu awon ilu ti A ti pare! Iya Wa de ba won ni oru tabi nigba ti won n sun oorun osan lowo

[5] Igbe enu won ko je kini kan nigba ti iya Wa de ba won ju pe won wi pe: "Dajudaju awa je alabosi

[6] Nitori naa, dajudaju A oo bi awon ti A ranse si leere (nipa ijepe). Dajudaju A o si bi awon Ojise leere (nipa ijise)

[7] Dajudaju A oo royin (ise owo won) fun won pelu imo. Awa ko sai wa pelu won (pelu imo)

[8] Ododo ni osuwon Ojo yen. Nitori naa, enikeni ti awon osuwon (ise rere) re ba te won; awon wonyen, awon ni olujere

[9] Enikeni ti awon osuwon (ise rere) re ba fuye, awon wonyen ni awon t’o s’emi ara won lofo nitori pe won n sabosi si awon ayah Wa

[10] Dajudaju A fun yin ni ipo ati ibugbe lori ile. A si se ona ije-imu fun yin lori re. Die ni ope ti e n da

[11] Dajudaju A da yin, leyin naa A ya aworan yin, leyin naa A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki Adam." Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, ti ko si ninu awon oluforikanle

[12] (Allahu) so pe: "Ki ni o ko fun o lati fori kanle ki i nigba ti Mo pa a lase fun o." (Esu) wi pe: "Emi loore julo si oun; ina ni O fi da emi, O si da oun lati ara erupe amo

[13] (Allahu) so pe: "Sokale kuro nibi nitori pe ko letoo fun o lati segberaga nibi. Nitori naa, jade dajudaju iwo n be ninu awon eni yepere

[14] (Esu) wi pe: "Lo mi lara titi di ojo ti won yoo gbe awon eniyan dide

[15] (Allahu) so pe: "Dajudaju iwo n be ninu awon ti A oo lo lara

[16] (Esu) wi pe: "Fun wi pe O ti fi mi sinu anu, emi yoo jokoo de won ni ona taara Re

[17] Leyin naa, dajudaju emi yoo wa ba won lati iwaju won, lati eyin won, lati otun won ati osi won. Iwo ko si nii ri opolopo won ni oludupe (fun O)

[18] (Allahu) so pe: "Jade kuro nibi (ki o si di) alabuku, eni-aledanu. Dajudaju enikeni t’o ba tele o ninu won, dajudaju Emi yoo fi gbogbo yin kun inu ina Jahanamo

[19] Adam, ki iwo ati iyawo re maa gbe ninu Ogba Idera. Nitori naa, e maa je nibikibi ti e ba fe. Ki e si ma se sunmo igi yii nitori ki e ma baa wa ninu awon alabosi

[20] Esu si ko royiroyi ba awon mejeeji nitori ki o le fi ohun ti A fi pamo ninu ihoho ara won han won. O si wi pe: "Oluwa eyin mejeeji ko ko igi yii fun yin bi ko se pe ki eyin mejeeji ma baa di molaika tabi ki eyin mejeeji ma baa di olusegbere

[21] O si bura fun awon mejeeji pe: "Dajudaju emi wa ninu awon onimoran fun eyin mejeeji

[22] O si tan awon mejeeji je. Nigba ti awon mejeeji to igi naa wo, ihoho awon mejeeji si han sira won. Won ba bere si fi awon ewe Ogba Idera bora won. Oluwa awon mejeeji si pe won pe: "Nje Emi ko ti ko igi naa fun eyin mejeeji? (Se) Emi ko si ti so fun eyin mejeeji pe ota ponnbele ni Esu je fun yin

[23] Awon mejeeji so pe: "Oluwa wa, a ti sabosi si emi wa. Ti O o ba forijin wa, ki O si ke wa, dajudaju a maa wa ninu awon eni ofo." gege bi won tun se gbagbo pe eje Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) lori igi agbelebuu ti pa awon ese miiran re fun gbogbo awon t’o gbagbo ninu Jesu Kristi ati eje re lori igi agbelebuu. Allahu si so pe eleru-ese kan ko nii ru eru-ese elomiiran mo tire. Ikerin; awon kristieni di olusina nipa bi won se so Anabi ‘Isa omo Moryam ati iya re di olohun ti won n josin fun nitori pe won gba pe ikini keji won nikan ni ko ni egun ese eso jije lorun ati pe won tun gbagbo pe Hawa’ (rodiyallahu 'anha) je eso igi naa. Jije re si je ese lorun awon mejeeji nikan ko si ese eso jije lorun awon omo won kan kan. Koko keji: awon mejeeji toro aforijin lori asise naa ti won si so gbogbo omo re di elese eso nipase re ohun ni pe

[24] (Allahu) so pe: "E sokale, ota ni apa kan yin fun apa kan. Ibugbe ati nnkan igbadun si n be fun yin ni ori ile fun igba (die).”

[25] (Allahu) so pe: “Lori ile ni eyin yoo ti maa semi, lori re ni eyin yoo maa ku si, A o si mu yin jade lati inu re.”

[26] Omo (Anabi) Adam, dajudaju A ti so aso kale fun yin, ti o maa bo ihoho yin ati ohun amusoro. Aso iberu Allahu, iyen l’o si loore julo. Iyen wa ninu awon ami Allahu nitori ki won le lo iranti

[27] Omo (Anabi) Adam, e ma se je ki Esu ko ifooro ba yin gege bi o se yo awon obi yin mejeeji jade kuro ninu Ogba Idera. O gba aso kuro lara awon mejeeji nitori ki o le fi ihoho won han won. Dajudaju o n ri yin; oun ati awon omo ogun re (n ri yin) ni aye ti eyin ko ti ri won. Dajudaju Awa fi Esu se ore fun awon ti ko gbagbo

[28] Nigba ti won ba si se ibaje kan, won a wi pe: "A ba awon baba wa lori re ni. Allahu l’O si pa a lase fun wa." So pe: "Dajudaju Allahu ki i p’ase ibaje. Se e fe safiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu ni

[29] So pe: “Oluwa mi p’ase sise deede. Ki e si doju yin ko (Allahu) ni gbogbo mosalasi. E pe E (ki e je) olusafomo-esin fun Un. Gege bi O se da yin (ti e fi di alaaye), e maa pada (di alaaye leyin iku yin).”

[30] Apa kan ni O fi mona, apa kan si ni isina ko le lori. (Nitori pe) dajudaju won mu awon esu ni ore leyin Allahu. Won si n lero pe dajudaju awon ni olumona

[31] Omo (Anabi) Adam, e wo (aso) oso yin nigbakigba ti e ba n lo si mosalasi. E je, e mu, ki e si ma yapa. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon apa

[32] So pe: “Ta l’o se oso Allahu, ti O mu jade fun awon erusin Re ati awon nnkan daadaa ninu arisiki ni eewo?” So pe: “O wa fun awon t’o gbagbo lododo ninu isemi aye. Tiwon nikan si ni l’Ojo Ajinde." Bayen ni A se n salaye awon ayah fun ijo t’o nimo.”

[33] So pe: "Ohun ti Oluwa mi se ni eewo ni awon iwa ibaje – eyi t’o foju han ninu re ati eyi t’o pamo –, iwa ese, ote sise lai letoo, biba Allahu wa akegbe – eyi ti ko so eri kan kale fun – ati sise afiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu

[34] Akoko kan ti wa fun ijo kookan; nigba ti akoko won ba si de, won ko le sun un siwaju di akoko kan, won ko si le fa a seyin

[35] Omo (Anabi) Adam, nigba ti awon Ojise ninu yin ba wa ba yin, ti won yoo maa ka awon ayah Mi fun yin, enikeni ti o ba beru (Mi), ti o si satunse, ko nii si iberu kan fun won, won ko si nii banuje

[36] Awon t’o ba si pe awon ayah Wa niro, ti won si segberaga si i, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

[37] Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu tabi t’o pe awon ayah Re niro? Ipin awon wonyen ninu kadara yoo maa te won lowo titi di igba ti awon Ojise Wa yoo wa ba won, ti won yoo gba emi won. Won yo si so pe: "Nibo ni awon nnkan ti eyin n pe leyin Allahu wa?" Won yoo wi pe: “Won ti di ofo mo wa lowo." Won si jerii lera won lori pe dajudaju awon je alaigbagbo.”

[38] (Allahu) so pe: "E wole ti awon ijo t’o ti re koja lo siwaju yin ninu awon alujannu ati eniyan (ti won ti wa) ninu Ina." Igbakigba ti ijo kan ba wo (inu Ina), won yoo maa sebi fun awon ijo re (t’o ti wa nibe siwaju won), titi di igba ti gbogbo won yoo fi pade ara won ninu Ina. (Igba yii ni) awon eni ikeyin won yoo wi fun awon eni isaaju won pe: "Oluwa wa, awon wonyi ni won si wa lona. Nitori naa, fun won ni ilopo iya meji ninu Ina." (Allahu) so pe: "Ikookan (yin) l’o ni ilopo iya, sugbon eyin ko mo

[39] Awon eni akoko won yo si wi fun awon eni ikeyin won pe: "Ko si ajulo kan fun yin lori wa. Nitori naa, e to Iya wo nitori ohun ti e n se nise

[40] Dajudaju awon t’o pe awon ayah Wa niro, ti won si segberaga si i, Won ko nii si awon ilekun sanmo fun won. Won ko si nii wo inu Ogba Idera titi rakunmi yoo wo inu iho abere. Bayen ni A se n san awon elese ni esan

[41] Ite wa fun won ninu ina Jahanamo. Orule si wa fun won ni oke won. Bayen ni A se n san awon alabosi ni esan

[42] Awon t’o si gbagbo lododo, ti won si se awon ise rere - A ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re - awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re

[43] A o si mu inunibini kuro ninu okan won. Awon odo yo si maa san ni isale won. Won yoo so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O fi wa mona yii. Awa iba ti mona, ti ki i ba se pe Allahu to wa si ona. Dajudaju awon Ojise Oluwa wa ti mu ododo wa.” Won si maa pe won pe: “Iyen ni Ogba Idera ti A jogun re fun yin nitori ohun ti e n se nise.”

[44] Awon ero inu Ogba Idera yoo pe awon ero inu Ina pe: "A ti ri ohun ti Oluwa wa se adehun re fun wa ni ododo. Nje eyin naa ri ohun ti Oluwa yin se adehun (re fun yin) ni ododo?" Won yoo wi pe: “Bee ni.” Olupepe kan yo si pepe laaarin won pe: "Ki ibi dandan Allahu maa be lori awon alabosi

[45] (Awon ni) awon t’o n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won si n fe ko wo. Awon si tun ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin

[46] Gaga yoo wa laaarin ero inu Ogba Idera ati ero inu Ina. Awon eniyan kan maa wa lori ogiri (gaga naa), won yo si da eni kookan (ijo mejeeji) mo pelu ami won. Won yoo pe awon ero inu Ogba Idera pe: “Ki alaafia maa be fun yin.” Won ko i wo (inu) re, won si ti n jerankan (re)

[47] Nigba ti won ba yiju won si ogangan awon ero inu Ina, won yoo so pe: “Oluwa wa, ma fi wa sodo awon ijo alabosi.”

[48] Awon ero ori ogiri (gaga naa), yoo pe awon eniyan kan ti won mo won pelu ami won, won yo si so pe: “Ohun ti e kojo nile aye ati sise igberaga yin si igbagbo ododo ko ro yin loro mo (bayii)”

[49] (Allahu) yoo so fun ero inu Ina pe: “Se awon (ero ori ogiri) wonyi ni eyin n bura pe Allahu ko nii siju aanu wo? (Nitori naa, eyin ero ori ogiri) e wo inu Ogba Idera. Ko nii si iberu kan fun yin. Eyin ko si nii banuje.”

[50] Ero inu Ina yoo pe ero inu Ogba Idera pe: “E fun wa ninu omi tabi ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin.” Won yoo so pe: “Dajudaju Allahu ti se mejeeji ni eewo fun awon alaigbagbo.”

[51] Awon t’o so esin won di iranu ati ere sise, isemi aye si ko etan ba won, ni oni ni A oo gbagbe won gege bi won se gbagbe ipade ojo won ti oni yii ati (bi) won se n tako awon ayah Wa

[52] A kuku ti mu tira kan wa ba won, ti A salaye re pelu imo. (O je) imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo

[53] Ki ni won n reti bi ko se imuse oro Re? Lojo ti imuse oro Re ba de, awon t’o gbagbe re siwaju yoo wi pe: “Dajudaju awon Ojise Oluwa wa ti mu ododo wa. Nitori naa, nje a le ri awon olusipe, ki won wa sipe fun wa tabi ki won da wa pada sile aye, ki a le se ise miiran yato si eyi ti a maa n se?” Dajudaju won ti se emi won lofo. Ohun ti won si n da ni adapa iro ti di ofo mo won lowo

[54] Dajudaju Oluwa yin ni Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O n fi oru bo osan loju, ti oru n wa osan ni kiakia. Oorun, osupa ati awon irawo ni won ti ro pelu ase Re. Gbo! TiRe ni eda ati ase. Ibukun ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda

[55] E pe Oluwa yin pelu iraworase ati ohun jeeje. Dajudaju (Allahu) ko feran awon alakoyo

[56] E ma sebaje lori ile leyin atunse re. E pe Allahu pelu iberu ati ireti. Dajudaju aanu Allahu sunmo awon oluse-rere

[57] Oun ni Eni t’O n ran ategun (t’o je) iro idunnu siwaju aanu Re, titi (ategun naa) yoo fi gbe esujo t’o wuwo, ti A si maa wo o lo si oku ile. Nigba naa, A maa fi so omi kale. A si maa mu orisirisi eso jade. Bayen ni A o se mu awon oku jade nitori ki e le lo iranti

[58] (Ile) ilu t’o dara, awon irugbin re yoo jade pelu ase Oluwa re. Eyi ti ko si dara, (irugbin re) ko nii jade afi (die) pelu inira. Bayen ni A se n mu awon ayah wa loniran-anran ona fun ijo t’o n dupe

[59] Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O si so pe: "Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Dajudaju mo n beru iya Ojo Nla fun yin

[60] Awon agbaagba ninu ijo re wi pe: "Dajudaju awa n ri o pe o wa ninu isina ponnbele

[61] O so pe: "Eyin ijo mi, ko si isina kan lodo mi, sugbon dajudaju emi ni Ojise kan lati odo Oluwa gbogbo eda

[62] Mo n je awon ise Oluwa mi fun yin. Mo n fun yin ni imoran rere. Ati pe ohun ti e o mo ni emi mo lati odo Allahu

[63] Ati pe se e seemo pe iranti lati odo Oluwa yin de ba yin ni, (eyi ti Won fun) okunrin kan ninu yin nitori ki o le kilo fun yin; nitori ki e le beru (Allahu) ati nitori ki A le ke yin

[64] Won si pe e lopuro. Nitori naa, A gba oun ati awon t’o wa pelu re la ninu oko oju-omi. A si te awon t’o pe awon ayah Wa niro ri. Dajudaju won je ijo t’o foju (si ododo)

[65] A tun ran (eni kan) si awon ara ‘Ad, arakunrin won, Hud. O so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Se e o nii beru (Re) ni

[66] Awon agbaagba t’o sai gbagbo ninu ijo re wi pe: “Dajudaju awa n ri o pe o wa ninu ago. Ati pe dajudaju a n ro pe o wa ninu awon opuro.”

[67] O so pe: "Eyin ijo mi, ko si ago kan lara mi, sugbon dajudaju emi ni Ojise kan lati odo Oluwa gbogbo eda

[68] Mo n je awon ise Oluwa mi fun yin. Emi si ni onimoran rere, olufokantan fun yin

[69] Ati pe se e seemo pe iranti lati odo Oluwa yin de ba yin ni, (eyi ti Won fun) okunrin kan ninu yin, nitori ki o le kilo fun yin? E ranti nigba ti (Allahu) fi yin se arole leyin ijo (Anabi) Nuh. O tun se alekun agbara fun yin ninu iseda (yin). Nitori naa, e ranti awon idera Allahu, nitori ki e le jere

[70] Won wi pe: “Se o wa ba wa nitori ki a le josin fun Allahu nikan soso ati nitori ki a le pa ohun ti awon baba nla wa n josin fun ti? Nitori naa, mu ohun ti o se ni ileri fun wa se ti o ba wa ninu awon olododo.”

[71] O so pe: “Iya ati ibinu kuku ti sokale sori yin lati odo Oluwa yin. Se e oo maa ja mi niyan nipa awon oruko (orisa) kan ti eyin ati awon baba yin fun loruko - Allahu ko si so eri kan kale fun un? – Nitori naa, e maa reti, dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”

[72] Nitori naa, pelu aanu lati odo Wa, A gba oun ati awon t’o wa pelu re la. A si pa awon t’o pe awon ayah Wa niro run; won ki i se onigbagbo ododo

[73] A tun ran (eni kan) si awon iran Thamud, arakunrin won, Solih. O so pe: "Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. Ise iyanu kuku ti de ba yin lati odo Oluwa yin; eyi ni abo rakunmi Allahu. (O je) ami kan fun yin. Nitori naa, e fi sile, ki o maa je kiri lori ile Allahu. E ma se fi owo aburu kan an nitori ki iya eleta-elero ma baa je yin

[74] E tun ranti nigba ti (Allahu) se yin ni arole leyin awon ara ‘Ad. O si fun yin ni ile igbe lori ile; e n ko ile nlanla sinu petele, e si n gbe awon ile sinu apata. E ranti awon idera Allahu, ki e si ma se rin lori ile ni ti obileje

[75] Awon agbaagba t’o segberaga ninu ijo re wi fun awon ti won foju tinrin, (iyen) awon t’o gbagbo lododo ninu won, pe: "Nje e mo pe dajudaju Solih ni Ojise lati odo Oluwa re?" Won so pe: “Dajudaju awa gbagbo ninu ohun ti Won fi ran an nise.”

[76] Awon t’o segberaga wi pe: “Dajudaju awa sai gbagbo ninu ohun ti eyin gbagbo.”

[77] Nitori naa, won gun abo rakunmi naa pa. Won si tapa si ase Oluwa won. Won si wi pe: “Solih, mu ohun ti o se ni ileri fun wa se ti o ba wa ninu awon Ojise.”

[78] Nitori naa, ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won

[79] Nigba naa, (Solih) seri kuro lodo won, o si so pe: “Eyin ijo mi, mo kuku ti je ise Oluwa mi fun yin. Mo si ti fun yin ni imoran rere sugbon eyin ko feran awon onimoran rere.”

[80] (Ranti Anabi) Lut, nigba ti o so fun ijo re pe: "Se e oo maa se ibaje ni ti ko si eni kan ninu awon eda t’o se iru re ri

[81] Dajudaju eyin (okunrin) n lo je adun (ibalopo) lara awon okunrin (egbe yin) dipo awon obinrin! Ani se, ijo alakoyo ni yin

[82] Ki si ni o je esi ijo re bi ko se pe, won wi pe: “E le won jade kuro ninu ilu yin, dajudaju won je eniyan kan t’o n fora won mo (nibi ese).”

[83] Nigba naa, A gba oun ati ebi re la afi iyawo re ti o wa ninu awon t’o seku leyin sinu iparun

[84] A ro ojo le won lori taara. Wo bi ikangun awon elese se ri

[85] (A tun ran eni kan) si awon ara Modyan, arakunrin won, Su‘aeb. O so pe: "Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. Dajudaju eri t’o yanju ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, e won kongo ati osuwon kun. E ma se din nnkan awon eniyan ku. E si ma se ibaje lori ile leyin atunse re. Iyen si loore julo fun yin ti e ba je onigbagbo ododo

[86] E ma se lugo si gbogbo ona lati maa deruba awon eniyan; e n seri eni t’o gbagbo kuro loju ona (esin) Allahu, e si n fe k’o wo. E ranti o, nigba ti e kere (lonka), Allahu so yin di pupo. E si wo bi ikangun awon obileje se ri

[87] Ti o ba je pe igun kan ninu yin gbagbo ninu ohun ti Won fi ran mi nise, ti igun kan ko si gbagbo, nigba naa e se suuru titi Allahu yoo fi se idajo laaarin wa. Oun si loore julo ninu awon oludajo

[88] Awon agbaagba t’o segberaga ninu ijo re wi pe: “Dajudaju a maa le iwo Su‘aeb ati awon t’o gbagbo pelu re jade kuro ninu ilu wa tabi e gbodo pada sinu esin wa.” (Su‘aeb) so pe: "Se (e maa da wa pada sinu iborisa) t’o si je pe emi wa ko o

[89] Dajudaju a ti da adapa iro mo Allahu ti a ba fi le pada sinu esin yin leyin igba ti Allahu ti yo wa kuro ninu re. Ati pe ko letoo fun wa lati pada sinu re afi ti Allahu, Oluwa wa ba fe. Oluwa wa gbooro tayo gbogbo nnkan pelu imo. Allahu l’a gbarale. Oluwa wa, se idajo laaarin awa ati ijo wa pelu ododo, Iwo si loore julo ninu awon oludajo

[90] Awon agbaagba t’o sai gbagbo ninu ijo re wi pe: “Dajudaju ti eyin ba tele Su‘aeb, nigba naa eyin ti di eni ofo niyen.”

[91] Nitori naa, ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won

[92] Awon t’o pe Su‘aeb lopuro si da bi eni ti ko gbe ninu ilu won ri; awon t’o pe Su‘aeb lopuro ni won je eni ofo

[93] Nitori naa, (Su‘aeb) seri kuro lodo won, o si so pe: “Eyin ijo mi, mo kuku ti je awon ise Oluwa mi fun yin. Mo si ti fun yin ni imoran rere. Bawo ni emi yoo se tun maa banuje lori ijo alaigbagbo.”

[94] A o ran Anabi kan si ilu kan lai je pe A fi iponju ati inira kan awon ara ilu naa nitori ki won le rawo-rase (si Allahu)

[95] Leyin naa, A fi (ohun) rere ropo aburu (fun won) titi won fi po (lonka ati loro). Won si wi pe: “Owo inira ati idera kuku ti kan awon baba wa ri.” Nitori naa, A gba won mu lojiji, won ko si fura

[96] Ti o ba je pe dajudaju awon ara ilu naa gbagbo lododo ni, ti won si beru (Allahu), A iba sina awon ibukun fun won lati inu sanmo ati ile. Sugbon won pe ododo niro. Nigba naa, A mu won nitori ohun ti won n se nise

[97] Se awon ara ilu naa faya bale pe iya Wa (ko le) de ba won ni ale ni, nigba ti won ba n sun lowo

[98] Se awon ara ilu naa faya bale pe iya Wa (ko le) de ba won ni iyaleta ni, nigba ti won ba n sere lowo

[99] Se won faya bale si ete Allahu ni? Ko ma si eni t’o maa faya bale si ete Allahu afi ijo olofo

[100] Se ko han si awon t’o jogun ile leyin awon onile pe ti o ba je pe A ba fe (bee ni), Awa iba fi ese won mu won, Awa iba si fi edidi bo okan won; won ko si nii gboro (mo)

[101] Awon ilu wonyi ni A n fun o ni iro ninu iroyin won. Dajudaju awon Ojise won ti mu awon eri t’o yanju wa ba won. (Ikookan ijo naa,) won ko kuku nii gbagbo ninu ohun ti (ijo t’o siwaju won) pe niro siwaju (won). Bayen ni Allahu se n fi edidi bo okan awon alaigbagbo

[102] Awa ko ri pipe adehun ni odo opolopo won. Ati pe nse ni A ri opolopo won ni obileje

[103] Leyin naa, A gbe (Anabi) Musa dide leyin won pelu awon ami Wa si Fir‘aon ati awon ijoye re. Won si se abosi si awon ami naa. Nitori naa, wo bi ikangun awon obileje se ri

[104] (Anabi) Musa so pe: "Fir‘aon, dajudaju emi ni Ojise kan lati odo Oluwa gbogbo eda

[105] Dandan ni fun mi pe emi ko nii safiti oro kan sodo Allahu afi ododo. Mo si kuku ti mu eri t’o yanju wa ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, je ki awon omo ’Isro’il maa ba mi lo

[106] (Fir‘aon) wi pe: “Ti o ba je eni t’o mu ami kan wa, mu un jade ti iwo ba wa ninu awon olododo.”

[107] Nigba naa, o ju opa re sile, o si di ejo ponnbele

[108] O tun fa owo re yo, o si di funfun (gbola) fun awon oluworan

[109] Awon ijoye ninu ijo Fir‘aon wi pe: "Dajudaju eyi ni onimo nipa idan pipa

[110] O fe ko yin kuro lori ile yin ni." (Fir‘aon wi pe: ) “Ki ni ohun ti e maa mu wa ni imoran?”

[111] Won si wi pe: "Da oun ati arakunrin re duro na, ki o si ran awon akonijo si awon ilu

[112] (pe) ki gbogbo onimo nipa idan pipa wa ba o

[113] Awon opidan si de wa ba Fir‘aon. Won wi pe: “Dajudaju esan gbodo wa fun wa ti awa ba je olubori.”

[114] O wi pe: “Bee ni. Ati pe dajudaju eyin gbodo wa ninu awon alasun-unmo (mi).”

[115] (Awon opidan) wi pe: “Musa, o maa (koko) ju opa sile ni, tabi awa ni a maa (koko) ju u sile.”

[116] (Anabi Musa) so pe: “E ju (tiyin) sile (na).” Nigba ti won ju u sile, won fi pidan loju awon eniyan. Won si seruba won. Won wa pelu idan nla

[117] A si fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Ju opa re sile.” Nigba naa, o si n gbe ohun ti won ti pa niro kale mi kalokalo

[118] Nitori naa, ododo de. Ohun ti won n se nise si baje

[119] Nitori naa, A bori won nibe yen. Won si dari wale ni eni yepere

[120] Ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan wole, ti won fori kanle (fun Allahu)

[121] Won so pe: "A gbagbo ninu Oluwa gbogbo eda

[122] Oluwa (Anabi) Musa ati Harun

[123] Fir‘aon wi pe: “E ti gba A gbo siwaju ki ng to yonda fun yin! Dajudaju eyi ni ete kan ti e ti hun ninu ilu nitori ki e le ko awon ara ilu jade kuro ninu re. Nitori naa, laipe e maa mo

[124] Dajudaju mo maa ge owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Leyin naa, dajudaju mo maa kan gbogbo yin mogi.”

[125] Won so pe: "Dajudaju odo Oluwa wa si ni a maa fabo si

[126] Ati pe o o tako kini kan lara wa lati fiya je wa bi ko se nitori pe a gba awon ami Oluwa wa gbo nigba ti o de ba wa. Oluwa wa, fun wa ni omi suuru mu. Ki O si pa wa sipo musulumi

[127] Awon ijoye ninu ijo Fir‘aon wi pe: "Se iwo yoo fi Musa ati awon eniyan re sile nitori ki won le sebaje lori ile ati nitori ki o le pa iwo ati awon orisa re ti?" (Fir‘aon) wi pe: "A oo maa pa awon omokunrin won ni. A o si maa da awon omobinrin won si. Dajudaju awa ni alagbara lori won

[128] (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "E fi Allahu wa iranlowo, ki e si se suuru. Dajudaju ti Allahu ni ile. O si n jogun re fun eni t’O ba fe ninu awon erusin Re. Igbeyin (rere) si wa fun awon oluberu (Allahu)

[129] Won so pe: “Won ni wa larasiwaju ki o to wa ba wa ati leyin ti o de ba wa.” (Anabi Musa) so pe: “O le je pe Allahu yoo pa awon ota yin run. O si maa fi yin ropo (won) lori ile. Nigba naa, (Allahu) yo si wo bi eyin naa yoo se maa se.”

[130] Dajudaju A gba eniyan Fir‘aon mu pelu oda ojo ati adinku t’o ba awon eso nitori ki won le lo iranti

[131] Nigba ti ohun rere ba de ba won, won a wi pe: “Tiwa ni eyi.” Ti aburu kan ba si sele si won, won a safiti aburu naa sodo (Anabi) Musa ati eni t’o wa pelu re. Kiye si i, ami aburu won kuku wa (ninu kadara won) lodo Allahu, sugbon opolopo won ni ko nimo

[132] Won si wi pe: “Ohunkohun ti o ba mu wa fun wa ni ami lati fi pidan fun wa, awa ko nii gba o gbo.”

[133] Nitori naa, A si fi ekun omi, awon esu, awon kokoro ina, awon opolo ati eje ranse si won ni awon ami ti n telera won, t’o foju han. Nse ni won tun segberaga; won si je ijo elese

[134] Nigba ti iya sokale le won lori, won wi pe: “Musa, pe Oluwa re fun wa nitori adehun ti O se fun o. Dajudaju ti o ba fi le gbe iya naa kuro fun wa (pelu adua re), dajudaju a maa gba o gbo, dajudaju a si maa je ki awon omo ’Isro’il maa ba o lo.”

[135] Nigba ti A gbe iya naa kuro fun won fun akoko kan ti won yoo lo (ninu isemi won), nigba naa ni won tun n ye adehun

[136] Nitori naa, A gbesan lara won, A si te won ri sinu agbami odo nitori pe won pe awon ayah Wa niro. Won si je afonufora nipa re

[137] A si jogun awon ibuyo oorun lori ile aye ati ibuwo oorun re, ti A fi ibunkun si, fun awon eniyan ti won foju tinrin. Oro Oluwa Re, t’o dara si ko le awon omo ’Isro’il lori nitori pe won se suuru. A si pa ohun ti Fir‘aon ati ijo re n se nise ati ohun ti won n ko nile run

[138] A mu awon omo ’Isro‘il la agbami odo ja. Nigba naa, won koja lodo awon eniyan kan ti won duro ti awon orisa won. Won si wi pe: “Musa, se orisa kan fun wa, gege bi awon (wonyi) se ni awon orisa kan.” (Anabi) Musa so pe: “Dajudaju eyin ni ijo alaimokan

[139] Dajudaju awon wonyi maa parun lori ohun ti won n se (yii). Iro si ni ohun ti won n se nise.”

[140] (Anabi) Musa so pe: "Se ki emi tun ba yin wa olohun kan ti eyin yoo maa josin fun leyin Allahu ni? Oun l’O si se ajulo oore fun yin lori awon eda (asiko yin)

[141] (E ranti) nigba ti A la yin lowo awon eniyan Fir‘aon ti won n fi iya buruku je yin, won n pa awon omokunrin yin taara, won si n da awon omobinrin yin si. Adanwo nla wa ninu iyen lati odo Oluwa yin

[142] Ati pe A yan ogbon oru fun (Anabi) Musa. A tun fi mewaa kun un. Nitori naa, akoko (ti) Oluwa Re (yoo fi ba a soro si maa) pari ni oru ogoji. (Anabi) Musa so fun arakunrin re, Harun, pe: “Role de mi laaarin awon eniyan mi. Ki o maa se atunse. Ma si se tele ona awon obileje.”

[143] Nigba ti (Anabi) Musa de ni akoko ti A fun un, Oluwa re si ba a soro. (Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, fi ara Re han mi, ki emi le ri O.” (Allahu) so pe: “Iwo ko le ri Mi. Sugbon wo apata (yii), ti o ba duro sinsin si aye re, laipe o maa ri Mi.” Nigba ti Oluwa re si (rora) fi ara Re han apata, O so o di petele. (Anabi) Musa si subu lule, o daku. Nigba ti o taji, o so pe: “Mimo ni fun O, emi ronu piwada si odo Re. Emi si ni akoko awon onigbagbo ododo (ni asiko temi)

[144] (Allahu) so pe: "Musa, dajudaju Emi sa o lesa lori awon eniyan pelu awon ise Mi ati oro Mi. Nitori naa, gba ohun ti Mo fun o mu. Ki o si wa ninu awon oludupe

[145] A si ko gbogbo nnkan fun un sinu awon walaa. (O je) waasi ati alaye oro fun gbogbo nnkan. Nitori naa, samulo re daradara. Ki o si pa ijo re lase pe ki won samulo nnkan daadaa t’o n be ninu re. Emi yoo fi ile awon arufin han yin

[146] Emi yoo seri awon t’o n segberaga lori ile lai letoo kuro nibi awon ami Mi. Ti won ba si ri gbogbo ami, won ko nii gba a gbo. Ti won ba ri ona imona, won ko nii mu un ni ona. Ti won ba si ri ona isina, won yoo mu un ni ona. Iyen nitori pe won pe awon ami Wa niro; won si je afonufora nipa re

[147] Awon t’o si pe awon ayah Wa ati ipade Ojo Ikeyin ni iro, awon ise won ti baje. Se A oo san won ni esan kan ni bi ko se ohun ti won n se nise

[148] Awon eniyan (Anabi) Musa, leyin re (nigba ti o fi lo ba Allahu soro), won mu ninu oso won (lati fi se) ere omo maalu oborogidi, o si n dun (bii maalu). Se won ko ri i pe dajudaju ko le ba won soro ni, ko si le fi ona mo won? Won si so o di akunlebo. Won si je alabosi

[149] Nigba ti o di abamo mo won lowo tan, won si ri i pe awon ti sina, won wi pe: “Ti Oluwa wa ko ba saanu wa, ki O si forijin wa, dajudaju awa yoo wa ninu awon eni ofo.”

[150] Nigba ti (Anabi) Musa si pada si odo ijo re pelu ibinu ati ibanuje, o so pe: “Ohun ti e fi role de mi leyin mi buru. Se e ti kanju pa ase Oluwa yin ti ni?" O si ju awon walaa sile, o gba ori arakunrin re mu, o si n wo o mora. (Harun) so pe: “Omo iya mi o, dajudaju awon eniyan ni won foju tinrin mi, won si fee pa mi. Nitori naa, ma se je ki awon ota yo mi. Ma si se mu mi mo ijo alabosi.”

[151] (Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, forijin emi ati arakunrin mi. Ki O si fi wa sinu ike Re. Iwo si ni Alaaanu-julo ninu awon alaaanu.”

[152] Dajudaju awon t’o so (ere) omo maalu di akunlebo, ibinu lati odo Oluwa won ati iyepere yoo ba won ninu isemi aye yii. Bayen ni A se n san awon aladapa iro ni esan

[153] Awon t’o si se awon ise aburu, leyin naa ti won ronu piwada leyin re, ti won si gbagbo ni ododo, dajudaju leyin eyi Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun

[154] Nigba ti ibinu (Anabi) Musa si wale, o mu awon walaa naa. Imona ati aanu n be ninu akosile re fun awon t’o n beru Oluwa won

[155] (Anabi) Musa si yan aadorin okunrin ninu ijo re fun akoko ti A fun un (lati wa toro aforijin fun awon eniyan re. Nigba ti won de ibi apata Sina’), ohun igbe lile t’o mi ile titi si gba won mu, o so pe: “Oluwa mi, ti O ba fe bee ni, Iwo iba ti pa awon ati emi re siwaju (ki a to wa sibi); se Iwo yoo pa wa re nitori ohun ti awon omugo ninu wa se ni? Ki ni ohun (ti won se) bi ko se adanwo Re; O n fi si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Iwo ni Alaabo wa. Nitori naa, forijin wa, ki O si ke wa. Iwo si loore julo ninu awon alaforijin

[156] Ki O si ko akosile rere fun wa ni aye yii ati ni orun. Dajudaju awa seri pada si odo Re.” (Allahu) so pe: “Iya Mi, Mo n fi je eni ti Mo ba fe. Ati pe ike Mi gbooro ju gbogbo nnkan lo. Emi yo si ko (ike Mi) mo awon t’o n beru (Mi), ti won si n yo Zakah ati awon ti won ni igbagbo ododo ninu awon ayah Wa.”

[157] Awon t’o n tele Ojise naa, Anabi alaimoonkomoonka, eni ti won yoo ba akosile nipa re lodo won ninu at-Taorah ati al-’Injil, ti o n pa won lase ohun rere, ti o n ko ohun buruku fun won, ti o n se awon nnkan daadaa letoo fun won, ti o si n se awon nnkan aidaa leewo fun won, ti o tun maa gbe eru (adehun t’o wuwo) ati ajaga t’o n be lorun won kuro fun won; awon t’o gbagbo ninu re, ti won bu iyi fun un, ti won ran an lowo, ti won si tele imole naa (iyen, al-Ƙur’an) ti A sokale fun un, awon wonyen ni olujere

[158] So pe: "Eyin eniyan, dajudaju emi ni Ojise Allahu si gbogbo yin patapata. (Allahu) Eni t’O ni ijoba awon sanmo ati ile. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Anabi alaimoonkomoonka, eni t’o gbagbo ninu Allahu ati awon oro Re. E tele e nitori ki e le mona

[159] O wa ninu ijo (Anabi) Musa, ijo kan t’o n fi ododo to (awon eniyan) sona. Won si n se eto pelu re

[160] A si pin won si iran mejila ni ijo-ijo. A si fi imisi ranse si (Anabi) Musa, nigba ti awon eniyan re wa omi wa si odo re, pe: “Fi opa owo re na apata.” (O se bee) orisun omi mejila si seyo lara re. Ijo kookan si ti da ibumu won mo. A tun fi esujo siji bo won. A so (ohun mimu) monnu ati (ohun jije) salwa kale fun won. E je ninu awon nnkan daadaa ti A pese fun yin. Won ko si se abosi si Wa, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

[161] (E ranti) nigba ti A so fun won pe: “E wo inu ilu yii. E maa je ninu re nibikibi ti e ba fe. Ki e si so pe: ‘Ha ese wa danu.’ E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba. A maa fori awon ese yin jin yin. A o si se alekun (esan rere) fun awon oluse-rere.”

[162] Awon t’o sabosi kuku yi oro naa pada si omiran ti o yato si eyi ti A so fun won. A si so iya kale lati sanmo le won lori nitori pe won n se abosi

[163] Bi won leere nipa ilu t’o wa ni ebado, nigba ti won koja enu-ala nipa ojo Sabt, nigba ti eja won n wa ba won ni ojo Sabt won, won si maa lefoo si oju odo, ojo ti ki i ba si se ojo Sabt won, won ko nii wa ba won. Bayen ni A se n dan won wo nitori pe won je obileje

[164] (Ranti) nigba ti ijo kan ninu won wi pe: “Nitori ki ni e fi n se waasi fun ijo kan ti Allahu maa pare tabi ti O maa je niya lile?” Won so pe: “(Ki o le je) awawi lodo Oluwa yin ati nitori ki won le beru (Allahu) ni.”

[165] Nigba ti won si gbagbe ohun ti won fi seranti fun won, A gba awon t’o n ko aburu la. A si fi iya t’o le je awon t’o sabosi nitori pe won je obileje

[166] Nigba ti won tayo enu-ala nibi ohun ti A ko fun won, A so fun won pe: “E di obo, eni igbejinna si ike.”

[167] (Ranti) nigba ti Oluwa re so o di mimo pe dajudaju Oun yoo gbe eni ti o maa fi iya buruku je won dide si won titi di Ojo Ajinde. Dajudaju Oluwa re ni Oluyara nibi iya. Dajudaju Oun si ni Alaforijin, Asake-orun

[168] A pin won lori ile si ijo-ijo; awon eni rere wa ninu won, awon miiran tun wa ninu won. A si fi awon ohun rere ati ohun buruku dan won wo ki won le seri pada (sibi ododo)

[169] Awon arole kan si role leyin won; won jogun Tira (Taorat ati ’Injil), won si n gba (abetele) oore ile aye yii (lati ko ikokuko sinu re), won si n wi pe: “Won yoo forijin wa.” Ti (abetele) oore iru re ba tun wa ba won, won maa gba a. Se A ko ti ba won se adehun ninu Tira pe won ko gbodo se afiti oro kan sodo Allahu afi ododo? Won si ti kekoo nipa ohun ti n be ninu re! Ile ikeyin si loore julo fun awon t’o n beru (Allahu). Se e o nii se laakaye ni

[170] Awon t’o n mu Tira lo daradara, ti won n kirun, dajudaju Awa ko nii fi esan awon t’o n se atunse (ise won) rare

[171] (Ranti) nigba ti A gbe apata ga soke ori won, o si da bi iboji. Won si lero pe o maa wo lu awon mole, (A si so fun won pe): “E gba ohun ti A fun yin mu daadaa, ki e si maa ranti ohun t’o n be ninu re, nitori ki e le beru (Allahu).”

[172] (Ranti) nigba ti Oluwa re gba adehun lowo awon omo Adam, O fa aromodomo won jade lati (ibadi ni) eyin (baba nla) won, O si fi won se elerii lori ara won pe: “Se Emi ko ni Oluwa yin ni?” Won so pe: “Rara – (Iwo ni Oluwa wa) - a jerii si i.” Nitori ki e ma baa so ni Ojo Ajinde pe: "Dajudaju awa je alaimo nipa eyi

[173] Tabi ki e ma baa wi pe: “Awon baba wa lo kuku ba Allahu wa akegbe siwaju (wa), awa si je aromodomo leyin won (ni a fi wo won kose pelu aimokan). Se Iwo yoo pa wa run nitori ohun ti awon t’o n tele iro se ni?”

[174] Bayen ni A se n salaye awon ayah Wa, nitori ki won le seri pada (sibi ododo)

[175] Ka iroyin eni ti A fun ni awon ayah Wa fun won, ti o yora re sile nibi awon ayah naa. Nitori naa, Esu tele e leyin. O si wa ninu awon olusina

[176] Ati pe ti o ba je pe A ba fe, Awa iba fi (imo nipa awon ayah Wa) sagbega fun un. Sugbon o waye moya. O si tele ife-inu re. Nitori naa, afiwe re da bi aja. Ti o ba le e siwaju, o maa yo ahon sita. Ti o ba si fi sile, o tun maa yo ahon sita. Iyen ni afiwe ijo t’o pe awon ayah Wa niro. So itan naa fun won nitori ki won le ronu jinle

[177] Ijo ti o pe awon ayah Wa niro, won buru ni afiwe. Ara won si ni won n sabosi si

[178] Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si si lona, awon wonyen, awon ni eni ofo

[179] Dajudaju A ti da opolopo eniyan ati alujannu fun ina Jahanamo (nitori pe) won ni okan, won ko si fi gbo agboye; won ni oju, won ko si fi riran; won ni eti, won ko si fi gboran. Awon wonyen da bi eran-osin. Won wule sonu julo. Awon wonyen, awon ni afonu-fora

[180] Ti Allahu ni awon oruko t’o dara julo. Nitori naa, e fi pe E. Ki e si pa awon t’o n ye kuro nibi awon oruko Re ti. A oo san won ni esan ohun ti won n se nise

[181] O wa ninu awon ti A da, ijo kan t’o n fi ododo to (awon eniyan) sona, won si n se eto pelu re

[182] Awon t’o si pe awon ayah Wa niro, A oo maa de won leke lati je won niya ni aye ti won ko nii mo

[183] Emi yoo lo won lara. Dajudaju ete Mi lagbara

[184] Se won ko ronu jinle ni? Ko si were kan kan lara eni won (iyen, Anabi s.a.w.). Ta si ni bi ko se olukilo ponnbele

[185] Se won ko wo ijoba awon sanmo ati ile pelu gbogbo nnkan ti Allahu da? Amo sa o le je pe Akoko iku won ti sunmo. Nigba naa, oro wo ni won yoo gbagbo leyin re? “oro wo ninu oro al-Ƙur’an ni won yoo gbagbo leyin ti ojo iku won ba de tabi leyin ti ojo Ajinde ba sele? Bi won ba pada gba oro al-Ƙu’an gbo lojo iku won tabi lojo Ajinde ko le wulo fun won mo oro iro wo ni won yoo gbagbo leyin ti al-Ƙur’an ti mu oro ododo wa? Se awon irori igba aimokan ati awon asa aimokan eyi ti iran eni kookan jogun ba lati odo awon baba nla won ti won ki i se Ojise Olohun se awon irori won ati awon asa iborisa won ni won yoo maa lo leyin al-Ƙur’an? Eyi gan-an ni itumo “fabi ’ayyi hadithin ba‘dahu yu’minun” ninu surah al-Jathiyah; 45:6 nitori pe gbolohun t’o siwaju re ni ibere ayah naa n soro nipa bi al-Ƙur’an se je oro ododo. Eyi wa tumo si pe

[186] Enikeni ti Allahu ba si lona ko le si afinimona kan fun un. (Allahu) yo si fi won sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida

[187] Won n bi o leere nipa Akoko naa pe igba wo ni isele re. So pe: “Odo Oluwa mi nikan ni imo re wa. Ko si eni t’o le safi han Akoko re afi Oun. O soro (lati mo) fun awon ara sanmo ati ara ile. Ko nii de ba yin afi lojiji.” Won tun n bi o leere bi eni pe iwo nimo nipa re. So pe: “Odo Oluwa mi nikan ni imo re wa, sugbon opolopo eniyan ni ko mo.”

[188] So pe: “Emi ko ni agbara anfaani tabi inira kan ti mo le fi kan ara mi ayafi ohun ti Allahu ba fe. Ti o ba je pe mo ni imo ikoko ni, emi iba ti ko ohun pupo jo ninu oore aye (si odo mi) ati pe aburu aye iba ti kan mi. Ta ni emi bi ko se olukilo ati oniroo idunnu fun ijo onigbagbo ododo.”

[189] (Allahu) Oun ni Eni t’O da yin lati ara emi eyo kan. O si da aya fun un lati ara re nitori ki o le jegbadun igbepo pelu re. Nigba ti oko sunmo iyawo re, ti o si ru eru (ato) fifuye. O si ru u kiri. Nigba ti o si diwo dise sinu tan, awon mejeeji pe Allahu Oluwa won pe: “Ti O ba fun wa ni omo rere (t’o pe ni eda), dajudaju a maa wa ninu awon oludupe.”

[190] Sugbon nigba ti Allahu fun awon mejeeji ni omo rere, won so (awon eda kan) di akegbe fun Un nipase ohun ti O fun awon mejeeji. Allahu si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I. ki eniyan wa so omo naa ni “ ‘abdu-ssams ‘abdul-ƙomor” dipo “ ‘abdullah bi o tile je pe Ibn Kathir ka itan naa mo ara itan iro awon omo Isro’il. Amo itan ti enu kun yii kuku ni awon ti won gba pe Anabi Adam (alaehi solat wa salam) ati iya wa Hawa’ (rodiyallahu anha) ni toko tiyawo ti isele naa sele si ri mu lo lati fi tumo ayah naa. Koko itan naa ni pe nigba ti iya wa Hawa’ (rodiyallahu 'anha) loyun amo ko fori bale fun Esu rara. Iyen wa ninu iwe Luku 4: 1-13. Nitori naa Allahu nikan soso ni ko le sasise

[191] Se won yoo so nnkan ti ko le da nnkan kan di akegbe Re, A si seda won ni

[192] Awon orisa ko le se aranse kan fun awon aborisa. Ati pe awon orisa gan-an ko le se aranse fun emi ara won

[193] Ti e ba pe won sibi imona, won ko nii tele yin. Bakan naa ni fun yin; e pe won tabi eyin dake enu (fun won)

[194] Dajudaju awon ti e n pe leyin Allahu, eru bi iru yin ni won. Nitori naa, e pe won wo, ki won da yin lohun ti e ba je olododo

[195] Se won ni ese ti won le fi rin ni? Tabi se won ni owo ti won le fi gba nnkan mu? Tabi se won ni oju ti won le fi riran? Tabi se won ni eti ti won le fi gboro? So pe: “E pe awon orisa yin, leyin naa ki e dete si mi, ki e si ma se lo mi lara

[196] Dajudaju Alatileyin mi ni Allahu, Eni ti O so Tira naa kale. Ati pe Oun l’O n satileyin fun awon eni rere

[197] Awon ti e n pe leyin Re, won ko le se aranse fun yin. Won ko si le se aranse fun emi ara won

[198] Ti e ba si pe won sinu imona, won ko nii gbo. O n ri won pe won n wo o ni, (sugbon) won ko riran

[199] Samojukuro, pase ohun rere, ki o si seri kuro lodo awon alaimokan

[200] Ti ibinu odi kan ba si seri sinu okan re lati odo Esu, sa di Allahu. Dajudaju Oun ni Olugbo, Onimo

[201] Dajudaju awon t’o beru (Allahu), nigba ti royiroyi kan ba sele si won lati odo Esu, ti won ba ranti (Allahu), nigba naa oju won yo si riran (ri ododo)

[202] (Amo ni ti) awon omo iya (Esu), nse ni awon Esu yoo maa kun won lowo ninu isina. Leyin naa, won ko si nii daran mo niwon

[203] Nigba ti o o ba mu ami wa ba won, won a wi pe: “Iwo ko se se adahun re?” So pe: “Ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi lati odo Oluwa mi ni mo n tele. (al-Ƙur’an) yii si ni awon eri t’o daju lati odo Oluwa yin. Imona ati ike si ni fun awon ijo onigbagbo ododo

[204] Nigba ti won ba n ke al-Ƙur’an, e teti si i, ki e si dake nitori ki A le ke yin

[205] Se iranti Oluwa Re ninu emi re pelu iraworase ati iberu (Allahu), ko si nii je oro ariwo, ni owuro ati asale. Iwo ko si gbodo wa ninu awon olugbagbera (nipa iranti Allahu)

[206] Dajudaju awon t’o n be lodo Oluwa re, won ki i jora won loju lati josin fun Un. Won n safomo fun Un. Won si n fori kanle fun Un

Ìkógun

Surah 8

[1] Won n bi o leere nipa oro ogun. So pe: “Oro ogun je ti Allahu ati ti Ojise. Nitori naa, e beru Allahu. Ki e si se atunse nnkan ti n be laaarin yin. E tele ti Allahu ati Ojise Re ti e ba je onigbagbo ododo

[2] Awon onigbagbo ododo ni awon t’o je pe nigba ti won ba fi (iya) Allahu se iranti (fun won), okan won yoo wariri, nigba ti won ba si ke awon ayah Re fun won, won yoo lekun ni igbagbo ododo. Oluwa won si ni won n gbarale

[3] (Awon ni) awon t’o n kirun, ti won si n na ninu ohun ti A pese fun won

[4] Ni ododo, awon wonyen ni onigbagbo ododo. Awon ipo giga, aforijin ati arisiki alapon-onle n be fun won lodo Oluwa won

[5] Gege bi Oluwa re se mu o jade (lo si oju ogun) lati inu ile re pelu ododo, dajudaju igun kan ninu awon onigbagbo ni emi won ko o

[6] Won si n tako o nibi ododo leyin ti o ti foju han (si won) afi bi eni pe won n wa won lo si odo iku, ti won si n wo o (bayii)

[7] (Ranti) nigba ti Allahu sadehun okan ninu awon ijo mejeeji fun yin pe o maa je tiyin, eyin si n fe ki ijo ti ko dira ogun je tiyin. Allahu si fe mu ododo se pelu awon oro Re, O si (fe) pa awon alaigbagbo run patapata

[8] nitori ki (Allahu) le fi ododo (’Islam) rinle ni ododo, ki O si le pana iro (iborisa), awon elese (osebo) ibaa korira re

[9] (Ranti) nigba ti e n wa iranlowo Oluwa yin, O si da yin lohun pe dajudaju Emi yoo ran yin lowo pelu egberun kan ninu awon molaika t’o maa wa ni telentele

[10] Allahu ko si se (iranlowo awon molaika) lasan bi ko se nitori ki o le je iro idunnu ati nitori ki okan yin le bale pelu re. Ko si aranse kan afi lati odo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

[11] (Ranti) nigba ti (Allahu) ta yin ni oogbe lo (ki o le je) ifokanbale (fun yin) lati odo Re. O tun so omi kale fun yin lati sanmo nitori ki O fi le fo yin mo (pelu iwe oran-anyan), ati nitori ki O fi le mu erokero Esu (bi ala ibalopo oju oorun) kuro fun yin ati nitori ki O le ki yin lokan ati nitori ki O le mu ese yin duro sinsin

[12] (Ranti) nigba ti Oluwa re fi mo awon molaika pe dajudaju Emi n be pelu yin. Nitori naa, e fi ese awon t’o gbagbo ni ododo rinle. Emi yoo ju eru sinu okan awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, e maa ge (won) loke orun. Ki e si maa ge gbogbo omo ika won

[13] Iyen nitori pe won tako (oro) Allahu ati Ojise Re. Enikeni ti o ba si tako (oro) Allahu ati Ojise Re, dajudaju Allahu le (nibi) iya

[14] Iyen (niya taye). Nitori naa, e to o wo. Ati pe dajudaju iya Ina n be fun awon alaigbagbo

[15] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba pade awon t’o sai gbagbo, ti won n wo jade niko niko, eyin ko gbodo peyin da si won (lati sagun)

[16] Enikeni ti o ba si peyin da si won ni ojo yen, yato si eni t’o ye si egbe kan (lati tunra mu) fun ogun tabi eni t’o fe darapo mo iko (musulumi lati fun won ni iro otele-muye), dajudaju (asagun) ti pada wale pelu ibinu lati odo Allahu. Ina Jahanamo si ni ibugbe re. Ikangun naa si buru

[17] Eyin ko l’e pa won, sugbon Allahu l’O pa won. Ati pe iwo ko l’o juko nigba ti o juko, amo dajudaju Allahu l’O juko nitori ki (Allahu) le fi amiwo daadaa kan awon onigbagbo ododo lati odo Re ni. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

[18] Iyen (bayen). Dajudaju Allahu maa so ete awon alaigbagbo di lile

[19] Ti eyin (alaigbagbo) ba n wa idajo, dajudaju idajo ti ko le yin lori. Ti e ba jawo (nibi ogun), o si dara julo fun yin. Ti e ba tun pada (sibi ogun), A maa pada (ran awon onigbagbo ododo lowo); akojo yin ko si nii ro yin loro kan kan, ibaa po. Dajudaju Allahu n be pelu awon onigbagbo ododo

[20] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele ti Allahu ati Ojise Re. E ma se gbunri kuro ni odo re nigba ti e ba n gbo (ayah) lowo

[21] E ma se da bi awon ti won wi pe: “A gbo.” Won ko si gbo

[22] Dajudaju eda abemi t’o buru julo ni odo Allahu ni awon aditi, ayaya ti ko se laakaye

[23] Ti o ba je pe Allahu mo oore kan lara won ni, iba je ki won gbo. Ti (Allahu) ba si fun won gbo ni, dajudaju won maa peyin da, won yo si maa gbunri

[24] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e jepe ti Allahu ati ti Ojise, nigba ti o ba pe yin sibi nnkan ti o maa mu yin semi. Ki e si mo pe dajudaju Allahu n sediwo laaarin eniyan ati okan re. Dajudaju odo Re si ni won maa ko yin jo si

[25] E sora fun adanwo kan ti ko nii mo lori awon t’o sabosi ninu yin nikan. Ki e si mo pe dajudaju Allahu le nibi iya

[26] E ranti pe nigba ti eyin kere, ti won n foju tinrin yin lori ile, ti e si n paya pe awon eniyan maa ji yin gbe lo, nigba naa (Allahu) se ibugbe fun yin (ninu ilu Modinah Onimoole), O si fi aranse Re se ikunlowo fun yin. O tun pese fun yin ninu awon nnkan daadaa nitori ki e le dupe

[27] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se janba (oran-anyan) Allahu ati (sunnah) Ojise; e ma se janba awon agbafipamo yin, e si mo (ijanba)

[28] Ki e si mo pe dajudaju ifooro ni awon dukia yin ati awon omo yin, ati pe dajudaju Allahu ni esan nla wa ni odo Re

[29] Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba beru Allahu, O maa fun yin ni ona abayo. O maa pa awon asise yin re fun yin. O si maa forijin yin. Allahu si ni Olola t’o tobi

[30] (Ranti) nigba ti awon t’o sai gbagbo n dete si o lati de o mole tabi lati pa o tabi lati yo o kuro ninu ilu; won n dete, Allahu si n dete. Allahu si loore julo ninu awon adete

[31] Nigba ti A ba n ke awon ayah Wa fun won, won a wi pe: “A kuku ti gbo. Ti o ba je pe a ba fe ni. awa naa iba so iru eyi. Ki ni eyi bi ko se akosile alo awon eni akoko.”

[32] (Ranti) nigba ti won wi pe: “Allahu, ti o ba je pe eyi ni ododo lati odo Re, ro ojo okuta le wa lori lati sanmo tabi ki O mu iya eleta-elero kan wa ba wa.”

[33] Allahu ko nii je won niya nigba ti iwo si n be laaarin won. Allahu ko si nii je won niya nigba ti won si n toro aforijin

[34] Ko si idi ti Allahu ko fi nii je won niya niwon igba ti won ba n se awon eniyan lori kuro ninu Mosalasi Haram. Ati pe awon osebo ko ni alamojuuto re. Ko si alamojuuto kan fun un bi ko se awon oluberu (Allahu), sugbon opolopo won ni ko mo

[35] Ijosin awon osebo ni Ile (Kaabah) ko si tayo sisu ife ati pipa atewo. Nitori naa, e to Iya wo nitori pe e je alaigbagbo

[36] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, won n na dukia won nitori ki won le seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Won si n na a lo (bee). Leyin naa, o maa di abamo fun won. Leyin naa, A si maa bori won. Ati pe awon t’o sai gbagbo, inu ina Jahanamo ni A maa ko won jo si

[37] nitori ki Allahu le ya awon eni ibi soto kuro lara awon eni ire ati nitori ki O le ko awon eni ibi papo; apa kan won mo apa kan, ki O si le ro gbogbo won papo patapata (soju kan naa), O si maa fi won sinu ina Jahanamo. Awon wonyen, awon ni eni ofo

[38] So fun awon t’o sai gbagbo pe ti won ba jawo (ninu aigbagbo), A maa saforijin ohun t’o ti re koja fun won. Ti won ba tun pada (sibe, apejuwe) iparun awon eni akoko kuku ti re koja (ni ikilo fun won)

[39] E ja won logun titi ko fi nii si ifooro (iborisa) mo, gbogbo esin yo si le je ti Allahu. Nitori naa, ti won ba jawo (ninu aigbagbo), dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

[40] Ti won ba si gbunri (kuro ninu igbagbo), e mo pe dajudaju Allahu ni Alafeyinti yin. O dara ni Alafeyinti. O si dara ni Alaranse

[41] E mo pe ohunkohun ti e ba ko ni oro ogun, dajudaju ti Allahu ni ida marun-un re. O si wa fun Ojise ati ebi (re) ati awon omo orukan, awon mekunnu ati onirin-ajo (ti agara da), ti e ba je eni t’o gbagbo ninu Allahu ati nnkan ti A sokale fun erusin Wa ni Ojo ipinya, ojo ti ijo meji pade (loju ogun Badr). Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[42] (E ranti) nigba ti eyin wa ni eti koto t’o sunmo (ilu Modinah), awon (keferi) si wa ni eti koto t’o jinna si (ilu Modinah), awon keferi kan t’o n gun nnkan igun (bo lati irin-ajo okowo), won si wa ni isale odo tiyin. Ti o ba je pe eyin ati awon keferi jo mu ojo fun ogun naa ni, eyin iba yapa adehun naa, sugbon (ogun naa sele bee) nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse; nitori ki eni ti o maa parun (sinu aigbagbo) le parun nipase eri t’o yanju, ki eni t’o si maa ye (ninu igbagbo ododo) le ye nipase eri t’o yanju. Ati pe dajudaju Allahu kuku ni Olugbo, Onimo

[43] (Ranti) nigba ti Allahu fi won han o ninu ala re (pe won) kere. Ti o ba je pe O fi won han o (pe won) po ni, eyin iba sojo, eyin iba si sariyanjiyan nipa oro naa. Sugbon Allahu ko (yin) yo. Dajudaju Oun ni Onimo nipa nnkan ti n be ninu igba-aya eda

[44] (Ranti) nigba ti O n fi won han yin pe won kere loju yin - nigba ti e pade (loju ogun) – O si mu eyin naa kere loju tiwon naa, nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

[45] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba pade ijo (ogun) kan, e duro sinsin, ki e si se (gbolohun) iranti Allahu ni (onka) pupo nitori ki e le jere

[46] E tele ti Allahu ati Ojise Re. E ma se jara yin niyan (nipa ogun esin) nitori ki e ma baa sojo ati nitori ki agbara yin ma baa kuro lowo yin. E se suuru, dajudaju Allahu wa pelu awon onisuuru

[47] E ma se da bi awon t’o jade kuro ninu ile won pelu faaari ati sekarimi. Won si n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise

[48] (Ranti) nigba ti Esu se ise won ni oso fun won, o si wi pe: “Ko si eni ti o maa bori yin lonii ninu awon eniyan. Dajudaju emi ni aladuugbo yin.” Sugbon nigba ti awon ijo ogun mejeeji foju kanra won, o pada seyin, o si fese fee, o wi pe: "Dajudaju emi ti yowo-yose ninu oro yin. Dajudaju emi n ri ohun ti eyin ko ri. Emi n paya Allahu. Allahu si le nibi iya

[49] (Ranti) nigba ti awon sobe-selu musulumi ati awon ti arun n be ninu okan won wi pe: “Esin awon wonyi tan won je.” Enikeni t’o ba gbarale Allahu, dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

[50] Ti o ba je pe iwo ri i nigba ti awon molaika ba n gba emi awon t’o sai gbagbo ni, ti won n lu oju won ati eyin won, (won si maa so fun won pe), “E to iya Ina jonijoni wo.”

[51] Iyen nitori ohun ti owo yin ti siwaju. Ati pe dajudaju Allahu ko nii se abosi fun awon eru (Re)

[52] (Isesi awon alaigbagbo) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won - won sai gbagbo ninu awon ayah Allahu. - Nitori naa, Allahu mu won nitori ese won. Dajudaju Allahu ni Alagbara, O le nibi iya

[53] Iyen nitori pe dajudaju Allahu ko nii se iyipada idera ti O se fun ijo kan titi won yoo fi se iyipada nnkan ti n be lodo ara won. Dajudaju Allahu si ni Olugbo, Onimo

[54] (Isesi awon alaimoore) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won, ti won pe awon ayah Oluwa won niro. Nitori naa, A pa won run nitori ese won; A si te awon eniyan Fir‘aon ri sinu agbami. Gbogbo won si je alabosi

[55] Dajudaju eda abemi t’o buru julo lodo Allahu ni awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, won ko nii gbagbo

[56] Awon ti o ba se adehun ninu won, leyin naa ti won n tu adehun won ni gbogbo igba, ti won ko si beru (Allahu)

[57] yala ti owo yin ba ba won loju ogun, (e pa won) ki e si (fi ogun) tu awon omoleyin won ka nitori ki won le lo iranti

[58] tabi ti o ba si n paya iwa ijanba lati odo ijo kan, ju adehun won sile fun won ki e di jo mo pe ko si adehun kan mo laaarin eyin mejeeji. Dajudaju Allahu ko nifee awon onijanba

[59] Ki awon t’o sai gbagbo ma se lero pe awon ti gbawaju. Dajudaju won ko le mori bo (ninu iya)

[60] E pese sile de won nnkan ija ti agbara yin ka ninu nnkan amusagbara ati awon esin ori iso, ti eyin yoo fi maa deru ba ota Allahu ati ota yin pelu awon miiran yato si won, ti eyin ko mo won – Allahu si mo won. – Ohunkohun ti e ba na loju ona (esin) Allahu, A oo san an pada fun yin ni kikun; A o si nii se abosi fun yin

[61] Ti won ba te sibi (eto) alaafia (fun dida ogun duro), iwo naa te sibe, ki o si gbarale Allahu. Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo

[62] Ti won ba tun fe tan o je, dajudaju Allahu a to o. Oun ni Eni ti O fi aranse Re ati awon onigbagbo ododo ran o lowo

[63] Allahu pa okan won po mora won. Ti o ba je pe o na gbogbo nnkan ti n be lori ile patapata, iwo ko le pa okan won po mora won. Sugbon Allahu pa okan won po mora won, dajudaju Oun ni Alagbara, Ologbon

[64] Iwo Anabi, Allahu ti to iwo ati awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo

[65] Iwo Anabi, gba awon onigbagbo ododo ni iyanju lori ogun esin. Ti ogun onisuuru ba wa ninu yin, won yoo bori igba. Ti ogorun-un ba si wa ninu yin, won yoo bori egberun ninu awon t’o sai gbagbo nitori pe dajudaju won je ijo ti ko gbo agboye

[66] Nisisin yii, Allahu ti se e ni fifuye fun yin. O si mo pe dajudaju ailagbara n be fun yin. Nitori naa, ti ogorun-un onisuuru ba wa ninu yin, won yoo bori igba. Ti egberun kan ba si wa ninu yin, won yoo bori egberun meji pelu ase Allahu. Allahu si wa pelu awon onisuuru

[67] Ko letoo fun Anabi kan lati ni eru ogun (ki o si tu won sile pelu owo itusile) titi o fi maa segun (won) tan patapata lori ile. Eyin n fe igbadun aye, Allahu si n fe orun. Allahu si ni Alagbara, Ologbon

[68] Ti ki i ba se ti akosile kan t’o ti gbawaju lati odo Allahu ni, owo iya nla ko ba te yin nipa nnkan ti e gba (ni owo itusile)

[69] Nitori naa, e je ninu ohun ti e ko ni oro ogun (ti o je) eto (ati) nnkan daadaa. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[70] Iwo Anabi, so fun awon t’o n be lowo yin ninu awon eru ogun pe, “Ti Allahu ba mo daadaa kan ninu okan yin, O maa fun yin ni ohun t’o dara ju ohun ti won gba lowo yin. O si maa forijin yin. Allahu si ni Alaforijin, Onikee.”

[71] Ti won ba si n gbero ijanba si o, won kuku ti janba Allahu siwaju. O si fun o lagbara lori won. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[72] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si fi dukia won ati emi won jagun loju ona (esin) Allahu, ati awon t’o gba won sodo (ninu ilu), ti won si ran won lowo; awon wonyen, apa kan won l’ore apa kan (t’o le jogun ara won). Awon t’o gbagbo, ti won ko si gbe ilu won ju sile, ko letoo fun yin lati mu won loree nibi kan kan (t’o le mu yin jogun ara yin), titi won yoo fi gbe ilu won ju sile. Ti won ba si wa iranlowo yin (lori ota) nipa esin, iranlowo naa di dandan fun yin ayafi lori ijo kan ti adehun n be laaarin eyin ati awon. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[73] Awon alaigbagbo; apa kan won ni alatileyin apa kan. Afi ki eyin naa se bee ni ifooro ati ibaje t’o tobi ko fi nii wa lori ile

[74] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si jagun l’oju ona (esin) Allahu ati awon t’o gba won sodo (ninu ilu), ti won si ran won lowo; ni ti ododo awon wonyen, awon ni onigbagbo ododo. Aforijin ati arisiki alapon-onle si wa fun won

[75] Awon t’o gbagbo ni ododo leyin (won), ti won gbe ilu won ju sile, ti won si jagun esin pelu yin, awon wonyen naa wa lara yin. Ati pe awon ibatan, apa kan won ni eto julo si apa kan (nipa ogun jije) ninu Tira Allahu. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

Ìrònúpìwàdà

Surah 9

[1] (Eyi ni) iyowo-yose lati odo Allahu ati Ojise Re si awon ti e se adehun fun ninu awon osebo

[2] Nitori naa, (eyin osebo) e rin (kiri) lori ile fun osu merin. Ki e si mo pe dajudaju eyin ko le moribo (ninu iya) Allahu. Ati pe dajudaju Allahu yoo doju ti awon alaigbagbo

[3] Ikede kan lati odo Allahu ati Ojise Re si awon eniyan ni ojo Hajj Nla ni pe, “Dajudaju Allahu yowoyose (ninu oro) awon osebo. Ojise Re naa (yowoyose). Ti e ba ronu piwada, o si loore julo fun yin. Ti e ba gbunri, e mo pe dajudaju e o le moribo ninu (iya) Allahu.” Ki o si fun awon t’o sai gbagbo ni iro iya eleta-elero

[4] Ayafi awon ti e ba se adehun ninu awon osebo, leyin naa, ti won ko si fi ona kan kan ye adehun yin, ti won ko si satileyin fun eni kan kan le yin lori. Nitori naa, e pe adehun won fun won titi di asiko won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re)

[5] Nitori naa, nigba ti awon osu owo ba lo tan , e pa awon osebo nibikibi ti e ba ti ba won. E mu won, e sede mo won, ki e si ba de won ni gbogbo ibuba. Ti won ba si ronu piwada, ti won n kirun, ti won si n yo Zakah, e yago fun won loju ona. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[6] Ti eni kan ninu awon osebo ba wa eto aabo wa sodo re, s’eto aabo fun un titi o fi maa gbo oro Allahu. Leyin naa, mu u de aye ifokanbale re. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko nimo

[7] Bawo ni adehun kan yoo se wa fun awon osebo lodo Allahu ati lodo Ojise Re yato si awon ti e ba se adehun nitosi Mosalasi Haram? Nitori naa, ti won ba duro deede pelu yin, e duro deede pelu won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re)

[8] Bawo (ni adehun kan yoo se wa fun won) nigba ti o je pe ti won ba bori yin, won ko nii so okun ibi ati adehun. Won n fi enu won wi pe awon yonu si yin, okan won si ko o. Opolopo won si ni obileje

[9] Won ta awon ayah Allahu ni owo pooku, won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Re. Dajudaju awon (wonyi), ohun ti won n se nise buru

[10] Awon osebo ko nii so okun ibi ati adehun kan fun onigbagbo ododo kan. Awon wonyen, awon si ni olutayo enu-ala

[11] Nitori naa, ti won ba ronu piwada, ti won n kirun, ti won si n yo Zakah, nigba naa omo-iya yin ninu esin ni won. A n salaye awon ayah naa fun ijo t’o nimo

[12] Ti won ba ru ibura won leyin adehun won, ti won si n soro aidara si esin yin, nigba naa e ja awon olori alaigbagbo logun - dajudaju ibura won ko ni itumo kan si won – ki won le jawo (nibi aburu)

[13] Se e o nii gbogun ti ijo kan t’o ru ibura won, ti won si gbero lati le Ojise kuro (ninu ilu); awon si ni won ko bere si gbogun ti yin ni igba akoko? Se e n paya won ni? Allahu l’O ni eto julo si pe ki e paya Re ti e ba je onigbagbo ododo

[14] E ja won logun. Allahu yoo je won niya lati owo yin. O maa yepere won. O maa ran yin lowo lori won. O si maa wo okan ijo onigbagbo ododo san

[15] O tun maa ko ibinu okan won lo. O si maa gba ironupiwada lowo eni t’O ba fe. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[16] Tabi e lero pe A oo fi yin sile lai je pe Allahu ti safi han awon t’o maa jagun esin ninu yin, ti won ko si ni ore ayo kan leyin Allahu, Ojise Re ati awon onigbagbo ododo? Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[17] Ko letoo fun awon osebo lati se amojuto awon mosalasi Allahu, nigba ti won je elerii si aigbagbo lori ara won. Awon wonyen ni ise won ti baje. Olusegbere si ni won ninu Ina

[18] Eni ti o maa samojuto awon mosalasi Allahu ni eni t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, t’o si n kirun, t’o n yo Zakah, ko si paya (orisa kan) leyin Allahu. Awon wonyen ni won kuku wa ninu awon olumona

[19] Se e maa se fifun alalaaji ni omi mu ati sise amojuto Mosalasi Haram ni ohun t’o dogba si eni t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, t’o si jagun soju ona (esin) Allahu? Won ko dogba lodo Allahu. Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

[20] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu, won tobi julo ni ipo lodo Allahu. Awon wonyen, awon si ni olujere

[21] Oluwa won n fun won ni iro idunnu nipa ike lati odo Re pelu iyonu ati awon Ogba Idera kan ti idera gbere wa fun won ninu re

[22] Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Dajudaju Allahu, odo Re ni esan nla wa

[23] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon baba yin ati awon arakunrin yin ni ore ayo bi won ba gbola fun aigbagbo lori igbagbo ododo. Enikeni t’o ba mu won ni ore ayo ninu yin, awon wonyen, awon ni alabosi

[24] So pe: “Ti o ba je pe awon baba yin, awon omokunrin yin, awon arakunrin yin, awon iyawo yin ati awon ibatan yin pelu awon dukia kan ti e ti ko jo ati okowo kan ti e n beru pe ki o ma kuta ati awon ibugbe ti e yonu si, (ti iwonyi) ba wu yin ju Allahu ati Ojise Re pelu jija ogun soju ona (esin) Re, e maa reti (ikangun) nigba naa titi Allahu yoo fi mu ase Re wa. Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje

[25] Dajudaju Allahu ti se aranse fun yin ni opolopo oju ogun ati ni ojo (ogun) Hunaen, nigba ti pipo yin jo yin loju, (amo) ko ro yin loro kan kan; ile si fun mo yin tohun ti bi o se fe to. Leyin naa, e peyin da, e si n sa seyin

[26] Leyin naa, Allahu so ifayabale Re kale fun Ojise Re ati fun awon onigbagbo ododo. O tun so awon omo ogun kan kale, ti e o foju ri won. O si je awon t’o sai gbagbo niya. Iyen si ni esan awon alaigbagbo

[27] Leyin naa, Allahu yoo gba ironupiwada lowo eni t’O ba fe leyin iyen. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[28] Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju egbin ni awon osebo. Nitori naa, won ko gbodo sunmo Mosalasi Haram leyin odun won yii. Ti e ba n beru osi, laipe Allahu maa ro yin loro ninu ola Re, ti O ba fe. Dajudaju Allahu ni Onimo, Ologbon

[29] E gbogun ti awon ti ko gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, awon ti ko se ni eewo ohun ti Allahu ati Ojise Re se ni eewo ati awon ti ko se esin ododo ninu awon ti A fun ni tira. (E gbogun ti won) titi won yoo fi maa fi owo ara won san owo-ori ni eni yepere

[30] Awon yehudi wi pe: "‘Uzaer ni omo Allahu." Awon nasara si wi pe: "Mosih ni omo Allahu." Iyen ni oro won ni enu won. Won n fi jo oro awon t’o sai gbagbo siwaju (won). Allahu fi won gegun-un. Bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo

[31] Won mu awon alufaa won (ninu yehudi) ati awon alufaa won (ninu nasara) ni oluwa leyin Allahu. (Won tun mu) Mosih omo Moryam (ni oluwa leyin Allahu). Bee si ni A o pa won lase kan tayo jijosin fun Olohun, Okan soso. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O mo tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[32] Won fe fi enu won pa imole (esin) Allahu, Allahu yo si ko (fun won) titi O fi maa pe imole (esin) Re, awon alaigbagbo ibaa korira re

[33] (Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (esin ’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re

[34] Eyin ti e gbagbo ni ododo, opolopo ninu awon alufaa (ninu yehudi) ati awon alufaa (ninu nasara), won kuku n fi ona eru je dukia awon eniyan ni, won si n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Awon t’o si n ko wura ati fadaka jo, won ko si na an fun esin Allahu, fun won ni iro iya eleta-elero

[35] Ni ojo ti A oo maa yo (wura ati fadaka naa) ninu ina Jahanamo, A o si maa fi jo iwaju won, egbe won ati eyin won. (A si maa so pe): "Eyi ni ohun ti e ko jo fun emi ara yin. Nitori naa, e to ohun ti e ko jo wo

[36] Dajudaju onka awon osu lodo Allahu n je osu mejila ninu akosile ti Allahu ni ojo ti O ti da awon sanmo ati ile. Merin ni osu owo ninu re. Iyen ni esin t’o fese rinle. Nitori naa, e ma sabosi si ara yin ninu awon osu owo. Ki gbogbo yin si gbogun ti awon osebo gege bi gbogbo won se n gbogun ti yin. Ki e si mo pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluberu (Re)

[37] Alekun ninu aigbagbo ni didajo si awon osu owo (lati owo awon osebo). Won n fi ko isina ba awon t’o sai gbagbo (nipa pe) won n se osu owo kan ni osu eto (fun ogun jija) ninu odun kan, won si n bu owo fun osu (ti ki i se osu owo) ninu odun (miiran, won ko si nii jagun ninu re) nitori ki won le yo onka osu ti Allahu se ni owo sira won. Won si tipase bee se ni eto ohun ti Allahu se ni eewo. Won se ise aburu won ni oso fun won. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo

[38] Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki ni o mu yin ti o fi je pe nigba ti A ba so fun yin pe ki e jade (lati jagun) loju ona (esin) Allahu, (igba naa ni) e maa kandi mole! Se e yonu si isemi aye (yii) ju ti orun ni? Igbadun isemi aye (yii) ko si je kini kan ninu ti orun afi die

[39] Afi ki e tu jade (sogun esin) ni Allahu ko fi nii je yin niya eleta-elero ati pe ni ko fi nii fi ijo to yato si yin paaro yin. E ko si le fi kini kan ko inira ba (Allahu). Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[40] Afi ki e ran an lowo, Allahu kuku ti ran an lowo nigba ti awon t’o sai gbagbo le e jade (kuro ninu ilu). O si je okan ninu awon meji.1 Nigba ti awon mejeeji wa ninu ogbun, ti (Anabi) si n so fun olubarin re pe: "Ma se banuje, dajudaju Allahu wa pelu wa."2 Nigba naa, Allahu so ifayabale Re kale fun un. O fi awon omo ogun kan ti e o foju ri ran an lowo. O si mu oro awon t’o sai gbagbo wale. Oro Allahu, ohun l’o si leke. Allahu si ni Alagbara, Ologbon

[41] E tu jade (fun ogun esin) pelu okun ati iroju. Ki e si fi awon dukia yin ati emi yin jagun fun esin Allahu. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo

[42] Ti o ba je pe nnkan igbadun (oro ogun) arowoto ati irin-ajo ti ko jinna (l’o pe won si ni), won iba tele o. Sugbon irin-ajo ogun Tabuk jinna loju won. Won yo si maa fi Allahu bura pe: “Ti o ba je pe a lagbara ni, awa iba jade (fun ogun esin) pelu yin.” – Won si n ko iparun ba emi ara won (nipa sise isobe-selu.) – Allahu si mo pe dajudaju opuro ni won

[43] Allahu ti samojukuro fun o. Ki lo mu o yonda fun won (pe ki won duro sile? Iwo iba ma se bee) titi oro awon t’o sododo yoo fi han si o kedere. Iwo yo si mo awon opuro

[44] Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin ko nii toro iyonda lodo re lati ma fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re)

[45] Awon t’o n toro iyonda lodo re (lati jokoo sile, dipo lilo si oju-ogun) ni awon ti ko gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin; okan won si n seyemeji. Nitori naa, won n daamu kiri nibi iseye-meji won

[46] Ti o ba je pe won gbero ijade fun ogun esin ni, won iba se ipalemo fun un. Sugbon Allahu korira idide won fun ogun esin, O si ko ifaseyin ba won. Won si so fun won pe: "E jokoo pelu awon olujokoo sile

[47] Ti o ba je pe won jade pelu yin, won ko nii kun yin afi pelu ibaje. Won yo si sare maa da rukerudo sile laaarin yin, ti won yoo maa ko yin sinu iyonu. Ati pe won ni olugboro fun won laaarin yin. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi

[48] Won kuku ti da iyonu sile teletele. Won si doju awon oro ru fun o titi ododo fi de, ti ase Allahu si foju han kedere; emi won si ko o

[49] O wa ninu won, eni ti n wi pe: “Yonda fun mi (ki ng jokoo sile); ma se ko mi sinu adanwo.” Inu adanwo (sisa fogun esin) ma ni won ti subu si yii. Dajudaju ina Jahanamo yo si kuku yi awon alaigbagbo po

[50] Ti daadaa ba sele si o, o maa ba won ninu je. Ti aida ba si sele si o, won a wi pe: “A kuku ti gba ase tiwa siwaju (lati jokoo sile.)” Won a peyin da; won yo si maa dunnu

[51] So pe: “Ko si ohun kan t’o maa sele si wa ayafi ohun ti Allahu ko mo wa. Oun ni Alaabo wa.” Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

[52] So pe: "Se e n reti kini kan pelu wa ni bi ko se okan ninu daadaa meji (iku ogun tabi isegun)? Awa naa n reti pelu yin pe ki Allahu mu iya kan wa ba yin lati odo Re tabi lati owo wa. Nitori naa, e maa reti, dajudaju awa naa wa pelu yin ti a n reti

[53] So pe: "E finnu-findo nawo ni tabi pelu tipatipa, A o nii gba a lowo yin (nitori pe) dajudaju eyin je ijo obileje

[54] Ko si si ohun kan ti ko je ki A gba inawo won lowo won bi ko se pe dajudaju won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Won ko nii wa kirun afi ki won je oroju alainikan-anse. Won ko si nii nawo fesin afi ki emi won ko o

[55] Nitori naa, ma se je ki awon dukia won ati awon omo won ya o lenu; Allahu kan fe fi je won niya ninu isemi aye (yii) ni. Emi yo si bo lara won, ti won maa wa nipo alaigbagbo

[56] Won n fi Allahu bura pe dajudaju awon kuku wa lara yin. Won ko si si lara yin, sugbon dajudaju won je ijo kan t’o n beru

[57] Ti o ba je pe won ri ibusasi kan, tabi awon iho apata kan, tabi ibusawo kan, won iba seri sibe ni werewere

[58] O tun wa ninu won, eni ti n da o lebi nibi (pipin) awon ore. Ti A ba fun won ninu re, won a yonu (si i). Ti A o ba si fun won ninu re, nigba naa ni won yoo maa binu

[59] Ati pe (iba loore fun won) ti o ba je pe dajudaju won yonu si ohun ti Allahu ati Ojise Re fun won, ki won si so pe: "Allahu to wa. Allahu yo si fun wa ninu oore ajulo Re ati pe Ojise Re (si maa pin ore) , dajudaju odo Allahu si ni awa n wa oore si

[60] Awon ti ore (Zakah) wa fun ni awon alaini, awon mekunnu, awon osise Zakah, awon ti okan won fe gba ’Islam, awon eru (fun gbigba ominira), awon onigbese, awon t’o wa loju ogun (esin) Allahu ati onirin-ajo (ti agara da). Oran-anyan ni lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[61] Awon t’o n ko inira ba Anabi wa ninu won, ti won si n wi pe: “Eleti-ofe ni." So pe: "Eleti-ofe rere ni fun yin; o gbagbo ninu Allahu. O si gba awon onigbagbo ododo gbo. Ike ni fun awon onigbagbo ododo ninu Ojise Allahu, iya eleta-elero n be fun won.”

[62] Won n fi Allahu bura fun yin lati wa iyonu yin. Allahu ati Ojise Re l’o si ye ki won wa iyonu Re ti won ba je onigbagbo ododo

[63] Se won ko mo pe enikeni t’o ba n tako Allahu ati Ojise Re, dajudaju ina Jahanamo ti wa fun un ni? Olusegbere si ni ninu re. Iyen si ni abuku nla

[64] Awon sobe-selu musulumi n beru pe ki A ma se so surah kan kale nipa won, ti o maa fun won ni iro ohun ti n be ninu okan won. So pe: "E maa se yeye lo. Dajudaju Allahu yoo safi han ohun ti e n beru

[65] Ti o ba kuku bi won leere, dajudaju won a wi pe: "Awa kan n rojo lasan ni, a si n sawada ni." So pe: "Se Allahu, awon ayah Re ati Ojise Re ni e n fi se yeye

[66] E ma se mu awawi wa. Dajudaju e ti sai gbagbo leyin igbagbo yin. Ti A ba se amojukuro fun apa kan ninu yin, A oo fiya je apa kan nitori pe won je elese

[67] Awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin, iru kan-un ni won; won n pase ohun buruku, won n ko ohun rere, won si n kawo gbera (lati nawo fesin). Won gbagbe Allahu. Nitori naa, Allahu gbagbe won. Dajudaju awon sobe-selu musulumi, awon ni obileje

[68] Allahu si ti se adehun ina Jahanamo fun awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin ati awon alaigbagbo. Olusegbere ni won ninu re. Ina maa to won. Allahu si ti sebi le won. Iya gbere si wa fun won

[69] (Awon sobe-selu musulumi da) gege bi awon t’o siwaju yin; won le ju yin lo ni agbara, won si po (ju yin lo) ni awon dukia ati awon omo. Nigba naa, won je igbadun ipin tiwon (ninu oore aye). Eyin (sobe-selu wonyii naa yoo) je igbadun ipin tiyin gege bi awon t’o siwaju yin se je igbadun ipin tiwon. Eyin naa si sosokuso bi eyi ti awon naa so ni isokuso. Awon wonyen, awon ise won ti baje ni aye ati ni orun. Awon wonyen, awon si ni eni ofo

[70] Se iroyin awon t’o siwaju won ko ti i de ba won ni? (Iroyin) ijo (Anabi) Nuh, iran ‘Ad, iran Thamud, ijo (Anabi) ’Ibrohim, awon ara Modyan ati awon ilu ti A doju re bole (ijo Anabi Lut); awon Ojise won wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Nitori naa, Allahu ko se abosi si won, sugbon emi ara won ni won sabosi si

[71] Awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, apa kan won lore apa kan; won n pase ohun rere, won n ko ohun buruku, won n kirun, won n yo Zakah, won si n tele ti Allahu ati Ojise Re. Awon wonyen ni Allahu yoo sake. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

[72] Allahu se adehun awon Ogba Idera fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. (O tun se adehun) awon ibugbe t’o dara ninu awon ogba idera ‘Adni (fun won). Iyonu lati odo Allahu l’o si tobi julo (fun won). Iyen, ohun ni erenje nla

[73] Iwo Anabi, gbogun ti awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Ki o si le mo won. Ina Jahanamo ni ibugbe won. Ikangun naa si buru

[74] Won n fi Allahu bura pe awon ko soro (buruku). Won si kuku ti so oro aigbagbo, won si sai gbagbo leyin ti won ti gba ’Islam. Won tun gberokero si nnkan ti owo won ko nii ba. Won ko tako kini kan bi ko se nitori pe Allahu ati Ojise Re ro awon (Sohabah) loro ninu ola Re. Ti won ba ronu piwada, o maa dara fun won. Ti won ba si koyin (si yin), Allahu yoo je won niya eleta-elero ni aye ati ni orun. Ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won lori ile aye

[75] O wa ninu won, eni t’o ba Allahu se adehun pe: "Ti O ba fun wa ninu oore-ajulo Re, dajudaju a oo maa tore, dajudaju a o si wa ninu awon eni ire

[76] Amo nigba ti O fun won ninu oore-ajulo Re, won sahun si I. Won peyin da, won si n gbunri (lati nawo fesin)

[77] Nitori naa, ahun won mu oro won kangun si isobe-selu ninu okan won titi di ojo ti won yoo pade Allahu nitori pe won ye adehun ti won ba Allahu se ati nitori pe won n paro

[78] Se won ko mo pe Allahu mo asiri won ati oro ateso won, ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa awon ikoko

[79] Awon t’o n bu awon olutore-aanu ninu awon onigbagbo ododo lori ore tita ati awon ti ko ri nnkan kan tayo iwon agbara won, won si n fi won se yeye, Allahu fi awon naa se yeye. Iya eleta-elero si wa fun won

[80] Yala o toro aforijin fun won tabi o o toro aforijin fun won – koda ki o toro aforijin fun won nigba aadorin – Allahu ko nii forijin won. Iyen nitori pe dajudaju won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje

[81] Awon olusaseyin fun ogun esin dunnu si jijokoo sinu ile won leyin Ojise Allahu. Won si korira lati fi dukia won ati emi won jagun loju ona (esin) Allahu. Won tun wi pe: “E ma lo jagun ninu ooru gbigbona.” So pe: “Ina Jahanamo le julo ni gbigbona, ti o ba je pe won gbo agboye oro.”

[82] Nitori naa, ki won rerin-in die, ki won si sunkun pupo; (o je) esan (fun) ohun ti won n se nise

[83] Ti Allahu ba mu o dele ba igun kan ninu won, ti won ba wa n gbase lodo re fun jijade fun ogun esin, so nigba naa pe: “Eyin ko le jade fun ogun esin mo pelu mi. Eyin ko si le ja ota kan logun mo pelu mi, nitori pe e ti yonu si ijokoo sile ni igba akoko. Nitori naa, e jokoo sile ti awon olusaseyin fun ogun esin.”

[84] Laelae, o o gbodo kirun si eni kan kan lara ninu won, ti o ba ku, o o si gbodo duro nibi saree re, nitori pe won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Won si ku nigba ti won wa nipo obileje

[85] Ma se je ki awon dukia won ati awon omo won ya o lenu; Allahu kan fe fi je won niya ninu isemi aye (yii) ni. (O si fe ki) emi bo lara won, nigba ti won ba wa nipo alaigbagbo

[86] Nigba ti A ba so surah kan kale pe ki won gbagbo ninu Allahu, ki won si jagun pelu Ojise Re, (nigba naa ni) awon oloro ninu won yoo maa toro iyonda lodo re, won a si wi pe: “Fi wa sile ki a wa pelu awon olujokoo sile.”

[87] Won yonu si ki won maa wa pelu awon olusaseyin fun ogun esin. A ti fi edidi di okan won pa; nitori naa, won ko nii gbo agboye

[88] Sugbon Ojise ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re, won fi dukia won ati emi won jagun esin. Awon wonyen, awon oore n be fun won. Awon wonyen, awon si ni olujere

[89] Allahu ti pese sile de won awon Ogba Idera kan ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen ni erenje nla

[90] Awon alawaawi ninu awon Larubawa oko wa (ba o) nitori ki won le yonda (ijokoo sile) fun won. Awon t’o si pe oro Allahu ati oro Ojise niro naa jokoo sile. Iya eleta-elero yo si fowo ba awon t’o sai gbagbo ninu won

[91] Ko si ese fun awon alailagbara, awon alaisan ati awon ti ko ri ohun ti won maa na ni owo (lati fi jagun esin) nigba ti won ba ti ni otito si Allahu ati Ojise Re. Ko si ibawi kan fun awon olotiito-inu se. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[92] Ko tun si ese fun awon ti (o je pe) nigba ti won ba wa ba o pe ki o fun awon ni nnkan ti awon yoo gun (lo soju ogun), ti o si so pe, “Ng o ri nnkan ti mo le fun yin gun (lo soju ogun), won maa pada pelu oju won ti yoo maa damije ni ti ibanuje pe won ko ri nnkan ti won maa na (lo soju ogun esin)

[93] Awon ti ibawi wa fun ni awon t’o n toro iyonda lodo re (lati jokoo sile, ti) won si je oloro, ti won yonu si ki won wa pelu awon olusaseyin fun ogun esin. Allahu ti fi edidi di okan won pa; nitori naa, won ko si mo

[94] Won yoo mu awawi wa fun yin nigba ti e ba dari de ba won. So pe: "E ma se mu awawi wa; a o nii gba yin gbo. Allahu kuku ti so awon oro yin fun wa. Allahu ati Ojise Re yo si ri ise (owo) yin. Leyin naa, A oo da yin pada si odo Onimo-ikoko ati gbangba. Nigba naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

[95] Won yoo maa fi Allahu bura fun yin nigba ti e ba dari de ba won, nitori ki e le pa won ti. Nitori naa, e pa won ti; dajudaju egbin ni won. Ina Jahanamo si ni ibugbe won. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise

[96] Won yoo maa bura fun yin nitori ki e le yonu si won. Ti e ba yonu si won, dajudaju Allahu ko nii yonu si ijo obileje

[97] Awon Larubawa oko le ninu aigbagbo ati isobe-selu. O si sunmo pe won ko mo awon enu-ala ohun ti Allahu sokale fun Ojise Re. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[98] Ati pe o wa ninu awon Larubawa oko eni ti o ka inawo t’o n na (fun esin) si owo oran. O si n reti apadasi aburu fun yin. Awon si ni apadasi aburu yoo de ba. Allahu si ni Olugbo, Onimo

[99] O tun wa ninu awon Larubawa oko, eni ti o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si so inawo t’o n na (fun esin) di awon isunmo Allahu ati (gbigba) adua (lodo) Ojise. Kiye si i, dajudaju ohun ni isunmo Allahu fun won. Allahu yo si fi won sinu ike Re. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[100] Awon asiwaju, awon eni akoko ninu awon Muhajirun ati awon ’Ansor pelu awon t’o fi daadaa tele won, Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). O tun pa lese sile de won awon Ogba Idera ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen ni erenje nla

[101] Awon sobe-selu musulumi kan n be ninu awon ti o wa ni ayika yin ninu awon Larubawa oko ati ninu awon ara ilu Modinah, ti won wonkoko mo isobe-selu. O o mo won, Awa l’A mo won. A oo je won niya ni ee meji. Leyin naa, A oo da won pada sinu iya nla

[102] Awon miiran jewo ese won. Won da ise rere po mo ise miiran t’o buru. Boya Allahu yoo gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[103] Gba ore (Zakah) ninu dukia won, ki o fi so won di eni mimo, ki o si fi se afomo fun won. Se adua fun won. Dajudaju adua re ni ifayabale fun won. Allahu si ni Olugbo, Onimo

[104] Se won ko mo pe dajudaju Allahu Oun l’O n gba ironupiwada lowo awon erusin Re, O si n gba awon ore, ati pe dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[105] So pe: "E sise. Allahu a ri ise yin, Ojise Re ati awon onigbagbo ododo naa (maa ri i). Won si maa da yin pada sodo Onimo-ikoko-ati-gbangba. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

[106] Won so oro awon yooku ro na fun ase Allahu; yala ki O je won niya tabi ki O gba ironupiwada won. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[107] Awon t’o ko mosalasi lati fi da inira ati aigbagbo sile ati lati fi se opinya laaarin awon onigbagbo ododo ati lati fi se ibuba fun awon t’o gbogun ti Allahu ati Ojise Re ni isaaju – dajudaju won n bura pe “A o gbero kini kan bi ko se ohun rere.” – Allahu si n jerii pe dajudaju opuro ni won

[108] Ma se duro (kirun) ninu re laelae. Dajudaju mosalasi ti won ba fi ipile re lele lori iberu Allahu lati ojo akoko l’o letoo julo pe ki o duro (kirun) ninu re. Awon eniyan t’o nifee lati maa se imora wa ninu re. Allahu si feran awon olusemora

[109] Nje eni ti o fi ipile ile mimo tire lele lori iberu Allahu ati iyonu (Re) l’o loore julo ni tabi eni ti o fi ipile ile mimo tire lele ni egbe kan leti ogbun t’o maa ye lule, ti o si maa ye e lese sinu ina Jahanamo? Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

[110] Ile won ti won mo kale ko nii ye ko iyemeji sinu okan won titi okan won yoo fi ja kelekele. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[111] Dajudaju Allahu ra emi awon onigbagbo ododo ati dukia won nitori pe dajudaju tiwon ni Ogba Idera. Won n jagun loju ona (esin) Allahu; won n pa ota esin, won si n pa awon naa. (O je) adehun lodo Allahu. (O je) ododo ninu at-Taorah, al-’Injil ati al-Ƙur’an. Ta si ni o le mu adehun re se ju Allahu? Nitori naa, e dunnu si okowo yin ti e (fi emi ati dukia yin) se. Iyen, ohun si ni erenje nla

[112] Awon oluronupiwada, awon olujosin (fun Allahu), awon oludupe (fun Allahu), awon alaaawe, awon oludawote-orunkun (lori irun), awon oluforikanle (fun Allahu), awon olupase-ohun rere, awon oluko-ohun buruku ati awon oluso-enu-ala ti Allahu gbekale, fun awon onigbagbo ododo (wonyi) ni iro idunnu (Ogba Idera)

[113] Ko ye fun Anabi ati awon t’o gbagbo lododo lati toro aforijin fun awon osebo, won ibaa je ebi, leyin ti o ti han si won pe dajudaju ero inu ina Jehim ni won

[114] Ati pe aforijin ti (Anabi) ’Ibrohim toro fun baba re ko si je kini kan bi ko se nitori adehun t’o se fun un. Sugbon nigba ti o han si i pe dajudaju ota Allahu ni (baba re), o yowo yose kuro ninu re. Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim ni oluraworase, olufarada

[115] Allahu ki i mu isina ba ijo kan, leyin igba ti O ti to won sona, titi (Allahu) yoo fi se alaye nnkan ti won maa sora fun fun won. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[116] Dajudaju Allahu l’o ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu

[117] Dajudaju Allahu ti gba ironupiwada Anabi, awon Muhajirun ati awon ’Ansor, awon t’o tele e ni akoko isoro leyin ti okan igun kan ninu won fee yi pada, (amo) leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Dajudaju Oun ni Alaaanu, Asake-orun fun won

[118] (O tun gba ironupiwada) awon meta ti A (so oro won ro ninu awon olusaseyin fun ogun Tabuk. Awon musulumi si deye si won) titi ile fi ha mo won tohun ti bi o se feju to. Oro ara won si su ara won. Won si mo (ni amodaju) pe ko si ibusasi kan ti awon fi le sa mo Allahu lowo afi ki won sa si odo Re. Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won nitori ki won le maa ronu piwada. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[119] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si wa pelu awon olododo

[120] Ko letoo fun awon ara ilu Modinah ati eni ti o wa ni ayika won ninu awon Larubawa oko lati sa seyin fun Ojise Allahu (nipa ogun esin. Ko si letoo fun won) lati feran emi ara won ju emi re. Iyen nitori pe dajudaju ongbe, inira tabi ebi kan ko nii sele si won loju ogun loju ona (esin) Allahu, tabi won ko nii te ona kan ti n bi awon alaigbagbo ninu, tabi owo won ko nii ba kini kan lara ota afi ki A fi ko ise rere sile fun won. Dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare

[121] Won ko si nii na owo kekere tabi pupo (fun ogun esin), tabi ki won la afonifoji kan ko ja afi ki A ko o sile fun won nitori ki Allahu le san won ni esan t’o dara julo nipa ohun ti won n se nise

[122] Gbogbo awon musulumi ko si gbodo da lo si oju ogun esin. Iba suwon ki igun kan ninu won ninu iko kookan jade lati wa agboye nipa esin, ki won si maa se ikilo fun awon eniyan won nigba ti won ba pada sodo won boya won yo le sora se

[123] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e gbogun ti awon t’o sunmo yin ninu awon alaigbagbo; ki won ri ilekoko lara yin. Ki e si mo pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluberu (Re)

[124] Nigba ti A ba si so surah kan kale, o n be ninu won eni ti o maa wi pe: “Ta ni ninu yin ni eyi le igbagbo (re) kun?” Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, (ayah naa) yo si le igbagbo (won) kun. Won yo si maa dunnu

[125] Ni ti awon ti aisan si wa ninu okan won, (ayah naa) yo si se alekun egbin si egbin won. Won yo si ku si ipo alaigbagbo

[126] Se won ko ri i pe A n dan won wo ni ee kan tabi ee meji ni odoodun. Leyin naa, won ko ronu piwada, won ko si lo iranti

[127] Ati pe nigba ti A ba so surah kan kale, apa kan won yoo wo apa kan loju (won yo si wi pe): “Se eni kan n wo yin bi?” Leyin naa, won maa peyinda. Allahu si pa okan won da (sodi) nitori pe dajudaju awon ni ijo kan ti ko gbo agboye

[128] Dajudaju Ojise kan ti wa ba yin lati aarin yin. Ohun ti o maa ko inira ba yin lagbara lara re. O n se akolekan (oore orun) fun yin; alaaanuati onikee ni fun awon oni gbagbo ododo

[129] Nitori naa, ti won ba peyinda, so pe: “Allahu to fun mi. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Oun ni mo gbarale. Oun si ni Oluwa Ite nla

Yúnùsì

Surah 10

[1] ’Alif Lam Ro. Iwonyi ni awon ayah Tira ogbon

[2] Se o je kayefi fun awon eniyan pe A fi imisi ranse si arakunrin kan ninu won, pe: “Se ikilo fun awon eniyan, ki o si fun awon t’o gbagbo ni iro idunnu pe esan rere (ise ti won se) siwaju ti wa ni odo Oluwa won.”? Awon alaigbagbo wi pe: “Dajudaju opidan ponnbele ma ni (Anabi) yii.”

[3] Dajudaju Oluwa yin ni Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O n seto oro (eda). Ko si olusipe kan afi leyin iyonda Re. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Se e o nii lo iranti ni

[4] Odo Re ni ibupadasi gbogbo yin. (O je) adehun Allahu ni ododo. Dajudaju Oun l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (sodo Re) nitori ki O le fi deede san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Awon t’o si sai gbagbo, ohun mimu gbigbona ati iya eleta-elero n be fun won nitori pe won sai gbagbo

[5] (Allahu) Oun ni Eni ti O se oorun ni itansan. (O se) osupa ni imole. O si diwon (irisi) re sinu awon ibuso nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro (ojo). Allahu ko da iyen bi ko se pelu ododo. O n salaye awon ayah fun ijo t’o nimo

[6] Dajudaju awon ami wa ninu itelentele ati iyato oru ati osan ati ohun ti Allahu da sinu awon sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n beru (Allahu)

[7] Dajudaju awon ti ko reti ipade Wa (ni orun), ti won yonu si isemi aye, ti okan won si bale dodo si (isemi aye yii) ati awon afonu-fora nipa awon ayah Wa

[8] awon wonyen, ibugbe won ni Ina nitori ohun ti won n se nise

[9] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, Oluwa won yoo fi igbagbo ododo won to won sona. Awon odo yo si maa san ni isale odo won ninu Ogba Idera

[10] Adua won ninu re ni “mimo ni fun O, Allahu”. Ikini won ninu re ni “alaafia”. Ipari adua won si ni pe “gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda”

[11] Ti o ba je pe Allahu n kanju mu aburu ba awon eniyan (nipase epe enu won, gege bi O se n) tete mu oore ba won (nipase adua), A iba ti mu opin ba isemi won. Nitori naa, A maa fi awon ti ko reti ipade Wa sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida

[12] Nigba ti inira ba kan eniyan, o maa pe Wa lori idubule re tabi ni ijokoo tabi ni inaro. Nigba ti A ba mu inira re kuro fun un, o maa te siwaju (ninu aigbagbo) bi eni pe ko pe Wa si inira ti o mu un. Bayen ni won se ni oso fun awon alakoyo ohun ti won n se nise

[13] A kuku ti pa awon iran kan re siwaju yin nigba ti won se abosi. Awon Ojise won mu awon eri t’o yanju wa ba won. Won ko si gbagbo. Bayen ni A se n san ijo elese ni esan

[14] Leyin naa, A se yin ni arole lori ile leyin won nitori ki A le wo bi eyin naa yoo se maa se

[15] Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa, t’o yanju fun won, awon ti ko reti ipade Wa (ni orun) yoo maa wi pe: “Mu Ƙur’an kan wa yato si eyi tabi ki o yi i pada.” So pe: “Ko letoo fun mi lati yi i pada lati odo ara mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi. Dajudaju emi n paya iya Ojo nla ti mo ba fi le yapa Oluwa mi.”

[16] So pe: “Ti o ba je pe Allahu ba fe ni, emi iba ti le ke al-Ƙur’an fun yin, ati pe Allahu iba ti fi imo re mo yin. Mo kuku ti lo awon odun kan laaarin yin siwaju (isokale) re, se e o se laakaye ni?”

[17] Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu tabi t’o pe awon ayah Re niro? Dajudaju awon odaran ko nii jere

[18] Won n josin fun ohun ti ko le ko inira ba won, ti ko si le se won ni anfaani leyin Allahu. Won si n wi pe: “Awon wonyi ni olusipe wa lodo Allahu.” So pe: “Se e maa fun Allahu ni iro ohun ti ko mo ninu awon sanmo ati ile ni?” Mimo ni fun Un, O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[19] Ki ni awon eniyan je (ni ipile) bi ko se ijo eyo kan (ijo ’Islam). Leyin naa ni won yapa enu. Ti ko ba je pe oro kan t’o ti siwaju lodo Oluwa re, Awa iba ti yanju ohun ti won n yapa enu si laaarin ara won

[20] Won n wi pe: “Ki ni ko je ki ami kan sokale fun un lati odo Oluwa re?” Nitori naa, so pe: “Ti Allahu ni ikoko. Nitori naa, e maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”

[21] Nigba ti A ba fun awon eniyan ni idera kan towo leyin ti inira ti fowo ba won, nigba naa ni won maa dete si awon ayah Wa. So pe: “Allahu yara julo nibi ete. Dajudaju awon Ojise Wa n se akosile ohun ti e n da lete.”

[22] (Allahu) Oun ni Eni ti O mu yin rin lori ile ati ni oju omi, titi di igba ti e ba wa ninu oko oju-omi, ti ategun t’o dara si n tuko won lo, inu won yo si maa dun si i. (Amo) ategun lile ko lu u, igbi omi de ba won ni gbogbo aye, won si lero pe dajudaju won ti fi (adanwo) yi awon po, won si pe Allahu pelu sise afomo-adua fun Un pe: “Dajudaju ti O ba fi le gba wa la nibi eyi, dajudaju a maa wa ninu awon oludupe.”

[23] Sugbon nigba ti O gba won la tan igba naa ni won tun n se ibaje kiri lori ile lai letoo. Eyin eniyan, dajudaju ibaje yin n be lori yin. (Ibaje yin si je) igbadun isemi aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi yin. A si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

[24] Apejuwe isemi aye da bi omi kan ti A sokale lati sanmo, ti awon irugbin ninu ohun ti eniyan ati awon eran-osin n je si gba a sara, titi di igba ti ile yoo fi loraa. O si mu oso (ara) re jade. Awon t’o ni i si lero pe awon ni alagbara lori re, (nigba naa ni) ase Wa de ba a ni oru tabi ni osan. A si so o di oko ti won fa tu danu bi eni pe ko si nibe rara ri ni ana. Bayen ni A se n salaye awon ayah fun ijo alarojinle

[25] Allahu n pepe si ile Alaafia. O si n to eni ti O ba fe si ona taara (’Islam)

[26] Rere ati alekun (oore) wa fun awon t’o se rere. Eruku tabi iyepere kan ko nii bo won loju mole. Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re

[27] Awon t’o si s’ise aburu, esan aburu bi iru re (ni esan won). Iyepere si maa bo won mole. Ko si alaabo kan fun won lodo Allahu. (Won maa da bi) eni pe won fi apa kan oru t’o sokunkun bo won loju pa. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

[28] Ati pe (ranti) Ojo ti A oo ko gbogbo won jo, leyin naa A oo so fun awon t’o ba Allahu wa akegbe pe: “E duro pa si aye yin, eyin ati awon orisa yin.” Nitori naa, A ya won si otooto. Awon orisa won si wi pe: “Awa ko ni e n josin fun

[29] Nitori naa, Allahu to ni Elerii laaarin awa ati eyin pe awa je alaimo nipa ijosin yin (ti e se fun wa).”

[30] Nibe yen, emi kookan maa da ohun t’o se siwaju mo. Won yo si da won pada sodo Allahu, Oluwa won, Ododo. Ohun ti won si n da ni adapa iro si maa dofo mo won lowo

[31] So pe: “Ta ni O n pese fun yin lati inu sanmo ati ile? Ta ni O ni ikapa lori igboro ati iriran? Ta ni O n mu alaaye jade lati ara oku, ti O tun n mu oku jade lati ara alaaye? Ta si ni O n se eto oro (eda)?” Won yoo wi pe: "Allahu" Nigba naa, so pe: "Se e o nii beru (Re) ni

[32] Iyen ni Allahu, Oluwa yin, Ododo. Ki si ni o n be leyin Ododo bi ko se isina? Nitori naa, bawo ni won se n seri yin kuro nibi ododo

[33] Bayen ni oro Oluwa re se wa si imuse lori awon t’o sebaje pe dajudaju won ko nii gbagbo

[34] So pe: "Nje o wa ninu awon orisa yin eni ti o le pile dida eda, leyin naa, ti o maa da a pada (si ipile re leyin iku)?" So pe: "Allahu l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (si ipile re leyin iku). Nitori naa, bawo ni won se n seri yin kuro nibi ododo

[35] So pe: "Nje o wa ninu awon orisa yin eni t’o n fini mona sibi ododo?" So pe: “Allahu l’O n fini mona sibi ododo. Nigba naa, se Eni t’O n fini mona sibi ododo l’o letoo julo si pe ki won maa tele ni tabi eni ti ko le da ona mo funra re afi ti A ba fi mona?” Nitori naa, ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii

[36] Opolopo won ko si ri kini kan tele bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si le roro kini kan niwaju ododo. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti won n se nise

[37] Al-Ƙur’an yii ki i se nnkan ti o se e dahun (lati odo elomiiran) leyin Allahu, sugbon o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re, o n se alaye (awon) Tira naa. Ko si iyemeji ninu re. (O wa) lati odo Oluwa gbogbo eda

[38] Tabi won n wi pe: "O hun un ni? So pe: "E mu surah kan bi iru re wa. Ki e si pe enikeni ti e ba le pe leyin Allahu, ti e ba je olododo

[39] Ko ri bee, won pe ohun ti won ko ni imo re niro ni. Ati pe imuse oro Re ko ti i de ba won (ni won fi pe e niro). Bayen ni awon t’o siwaju won se pe (oro Allahu) niro. Nitori naa, wo bi atubotan awon alabosi se ri

[40] O si n be ninu won eni t’o gba a gbo ni ododo. O tun n be ninu won eni ti ko gba a gbo. Oluwa re si ni Onimo-julo nipa awon obileje

[41] Ti won ba pe o ni opuro, so pe: “Temi ni ise mi. Tiyin ni ise yin. Eyin yowo yose ninu ohun ti mo n se nise. Emi naa si yowo yose ninu ohun ti e n se nise.”

[42] O si wa ninu won, awon t’o n teti si o. Se iwo l’o maa mu aditi gboro ni, bi o tile je pe won ki i se laakaye

[43] O tun n be ninu won eni t’o n wo o. Se iwo l’o maa fi afoju mona ni, bi o tile je pe won ki i riran

[44] Dajudaju Allahu ko nii fi kini kan sabosi si eniyan. Sugbon eniyan n sabosi si emi ara won

[45] Ati pe (ranti) Ojo ti (Allahu) yoo ko won jo afi bi eni pe won ko gbe ile aye ju akoko kan ninu osan. Won yo si dara won mo. Dajudaju awon t’o pe ipade Allahu niro ti sofo; won ko si je olumona

[46] O see se ki A fi apa kan eyi ti A se ni ileri fun won han o tabi ki A ti gba emi re (siwaju asiko naa), odo Wa kuku ni ibupadasi won. Leyin naa, Allahu ni Arinu-rode ohun ti won n se nise

[47] Ojise ti wa fun ijo kookan. Nitori naa, nigba ti Ojise won ba de, A oo sedajo laaarin won pelu deede; A o si nii sabosi si won

[48] Won n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo?”

[49] So pe: “Emi ko ni ikapa inira tabi oore kan fun emi ara mi afi ohun ti Allahu ba fe. Gbedeke akoko ti wa fun ijo kookan. Nigba ti akoko naa ba de, won ko nii sun un siwaju di akoko kan, won ko si nii fa a seyin.”

[50] So pe: "E so fun mi, ti iya Re ba de ba yin ni oru tabi ni osan? Ewo ninu re ni awon elese n wa pelu ikanju?”

[51] Se leyin igba ti o ba sele tan ni e maa gba a gbo? Se nisinsin yii (ni e oo gba a gbo), ti e si kuku ti n wa a pelu ikanju

[52] Leyin naa, A oo so fun awon t’o sabosi pe: “E to iya gbere wo.” Se A oo san yin ni esan kan bi ko se ohun ti e n se nise

[53] Won si n beere fun iro re lodo re pe, “se ododo ni?” So pe: “Bee ni. Mo fi Oluwa mi bura. Dajudaju ododo ni. Eyin ko si nii mori bo.”

[54] Ati pe ti o ba je pe gbogbo nnkan ti n be lori ile je ti emi kookan t’o sabosi, iba fi serapada (fun emi ara won nibi iya). Won yoo fi igbe abamo pamo nigba ti won ba ri Iya. A o se idajo laaarin won pelu deede; Won ko si nii sabosi si won

[55] Gbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Gbo! Dajudaju adehun Allahu ni ododo, sugbon opolopo won ko nimo

[56] O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

[57] Eyin eniyan, isiti kan lati odo Oluwa yin ti de ba yin. Iwosan ni fun nnkan t’o wa ninu awon igba-aya eda. Imona ati ike ni fun awon onigbagbo ododo

[58] So pe: “Pelu ajulo oore Allahu (iyen, al-Ƙur’an) ati aanu Re (iyen, ’Islam), nitori iyen ni ki won maa fi dunnu; o si loore julo si ohun ti awon (alaigbagbo) n ko jo (ninu oore aye).”

[59] So pe: “E so fun mi nipa awon nnkan ti Allahu sokale fun yin ninu arisiki, ti eyin funra yin se awon kan ni eewo ati eto. Se Allahu l’O yonda fun yin ni tabi e n da adapa iro mo Allahu?”

[60] Ki ni ero-okan awon t’o n da adapa iro mo Allahu ni Ojo Ajinde na? Dajudaju Allahu ni Olola-julo lori awon eniyan, sugbon opolopo won ni ki i dupe (fun Un)

[61] Iwo ko nii wa ninu ise kan, iwo ko si nii ke (ayah kan) ninu al-Ƙur’an, eyin ko nii se ise kan afi ki Awa je Elerii lori yin nigba ti e ba n se e. Kini kan ko pamo fun Oluwa re; ti o mo ni odiwon ina-igun ninu ile ati ninu sanmo, ki o tun kere ju iyen lo tabi ki o tobi ju u lo afi ki o wa ninu akosile t’o yanju

[62] Gbo, dajudaju awon ore Allahu, ko nii si iberu (iya orun) fun won, won ko si nii banuje (lori oore aye)

[63] (Awon ni) awon t’o gbagbo lododo, won si maa n beru (Allahu)

[64] Ti won ni iro idunnu ninu isemi aye (yii) ati ni Ojo Ikeyin. Ko si iyipada kan fun awon oro Allahu. Iyen, ohun ni erenje nla

[65] Ma se je ki oro (enu) won ba o ninu je. Dajudaju gbogbo agbara patapata n je ti Allahu. Oun ni Olugbo, Onimo

[66] Gbo, dajudaju ti Allahu ni enikeni t’o n be ninu awon sanmo ati enikeni t’o n be lori ile. Ki ni awon t’o n pe awon orisa leyin Allahu n tele na? Won ko tele (kini kan) bi ko se aroso. Won ko si se kini kan bi ko se pe won n paro

[67] Oun ni Eni t’O se oru fun yin nitori ki e le sinmi ninu re. (O se) osan ni (asiko) ti e oo riran (kedere). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro (ododo)

[68] Won wi pe: “Allahu so eda di omo.” - Mimo ni fun Un. Oun ni Oluroro. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. – Ko si eri kan lodo yin fun eyi. Se e fe safiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu ni

[69] So pe: “Dajudaju awon t’o n da adapa iro mo Allahu, won ko nii jere.”

[70] Igbadun bin-intin (le wa fun won) nile aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi won. Leyin naa, A oo fun won ni iya lile to wo nitori pe won n sai gbagbo

[71] Ka iroyin (Anabi) Nuh fun won. Nigba ti o so fun ijo re pe: “Eyin eniyan mi, ti o ba je pe iduro mi (pelu yin) ati bi mo se n fi awon ayah Allahu se isiti fun yin ba lagbara lara yin, nigba naa Allahu ni mo gbarale. Nitori naa, e pa imoran yin po, (ki e si ke pe) awon orisa yin. Leyin naa, ki ipinnu oro yin ma se wa ni bonkele laaarin yin. Leyin naa, ki e yanju oro mi. Ki e si ma se lo mi lara mo

[72] Ti e ba si koyin (si iranti), emi ko kuku toro owo-oya kan lowo yin. Ko si esan kan fun mi (nibi kan) bi ko se lodo Allahu. Won si ti pa mi lase pe ki ng wa ninu awon musulumi.”

[73] Nigba naa, won pe e ni opuro. Nitori naa, A gba a la, oun ati awon t’o n be pelu re ninu oko oju-omi. A si se won ni arole (lori ile). A si te awon t’o pe ayah Wa niro ri sinu agbami. Nitori naa, wo bi ikangun awon eni-akilo-fun se ri

[74] Leyin naa, A gbe awon Ojise kan dide si awon ijo won. Won si mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon naa ko kuku gbagbo ninu ohun ti (ijo Anabi Nuh) pe niro siwaju (won, iyen ni pe, iru kan-un ni won). Bayen ni A se n fi edidi bo okan awon alakoyo

[75] Leyin naa, leyin won A fi awon ami Wa ran (Anabi) Musa ati Harun nise si Fir‘aon ati awon ijoye re. Nigba naa, won segberaga. Won si je ijo elese

[76] Nigba ti ododo de ba won lati odo Wa, won wi pe: “Dajudaju eyi ni idan ponnbele.”

[77] (Anabi) Musa so pe: "Se nnkan ti eyin yoo maa wi nipa ododo ni pe idan ni nigba ti o de ba yin? Se idan si ni eyi bi? Awon opidan ko si nii jere

[78] Won wi pe: “Se o wa ba wa nitori ki o le seri wa kuro nibi ohun ti a ba awon baba wa lori re (ninu iborisa) ati nitori ki titobi si le je teyin mejeeji lori ile? Awa ko si nii gba eyin mejeeji gbo.”

[79] Fir‘aon wi pe: “E lo mu gbogbo awon onimo nipa idan pipa wa fun mi.”

[80] Nigba ti awon opidan si de, (Anabi) Musa so fun won pe: “E ju ohun ti e maa ju sile.”

[81] Nigba ti won ju u sile, (Anabi) Musa so pe: “Idan ni ohun ti e mu wa. Dajudaju Allahu si maa ba a je. Dajudaju Allahu ko si nii satunse ise awon obileje

[82] Allahu si maa mu ododo se pelu awon oro Re, awon elese ibaa korira re

[83] Nitori naa, ko si eni t’o gba (Anabi) Musa gbo afi awon aromodomo kan ninu awon eniyan re pelu iberu-bojo (won) si Fir‘aon ati awon ijoye won pe o maa fooro awon. Dajudaju Fir‘aon kuku segberaga lori ile. Ati pe, dajudaju o wa ninu awon alakoyo

[84] (Anabi) Musa so pe: “Eyin eniyan mi, ti e ba je eni t’o gbagbo ninu Allahu, Oun naa ni ki e gbarale ti e ba je musulumi.”

[85] Nitori naa, won so pe: "Allahu la gbarale. Oluwa wa, ma se wa ni adanwo fun ijo alabosi

[86] Ki O si fi aanu Re gba wa la lowo ijo alaigbagbo

[87] A si ranse si (Anabi) Musa ati arakunrin re pe: “Ki eyin mejeeji mu awon ibugbe fun awon eniyan yin si ilu Misro. Ki e si so ibugbe yin di ibukirun. Ki e si maa kirun. Ati pe, fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu.”

[88] (Anabi) Musa so pe: "Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O fun Fir‘aon ati awon ijoye re ni oso ati dukia ninu isemi aye. Oluwa wa, (O fun won) nitori ki won le seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Re. Oluwa wa, pa dukia won re, ki O si mu okan won le, ki won ma gbagbo mo titi won fi maa ri iya eleta-elero

[89] (Allahu) so pe: "Dajudaju Mo ti gba adua eyin mejeeji. Nitori naa, ki eyin mejeeji duro sinsin. E ma se tele oju ona awon ti ko nimo

[90] A mu awon omo ’Isro’il la agbami odo ja. Fir‘aon ati awon omo ogun re si gba to won leyin, ni ti abosi ati itayo enu-ala, titi iteri sinu agbami okun fi ba a. O si wi pe: “Mo gbagbo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Eni ti awon omo ’Isro’il gbagbo. Mo si wa ninu awon musulumi.”

[91] Se nisinsin yii, ti iwo ti yapa siwaju, ti o si wa ninu awon obileje

[92] Nitori naa, ni oni ni A oo gbe oku re jade si ori ile tente nitori ki o le je ami (feyikogbon) fun awon t’o n bo leyin re. Dajudaju opolopo ninu awon eniyan ma ni afonu-fora nipa awon ayah Wa

[93] A kuku se ibugbe fun awon omo ’Isro’il ni ibugbe alapon-onle. A si pese fun won ninu awon nnkan daadaa. Nigba naa, won ko yapa enu (si ’Islam) titi imo fi de ba won. Dajudaju Oluwa re yoo sedajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si

[94] Ti o ba wa ninu iyemeji nipa nnkan ti A sokale fun o (pe oruko re ati asotele nipa re wa ninu Taorat ati ’Injil), bi awon t’o n ka Tira siwaju re leere wo. Dajudaju ododo ti de ba o lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji

[95] O o gbodo wa lara awon t’o pe awon ayah Allahu niro, nitori ki o ma baa wa lara awon eni ofo

[96] Dajudaju awon ti oro Oluwa re ti ko le lori, won ko nii gbagbo

[97] gbogbo ayah ibaa de ba won, titi won maa fi ri iya eleta-elero

[98] Ko kuku si ilu kan, t’o gbagbo (lasiko iya), ti igbagbo re si se e ni anfaani afi ijo (Anabi) Yunus. Nigba ti won gbagbo, A mu abuku iya kuro fun won ninu isemi aye. A si je ki won je igbadun aye fun igba die

[99] Ti o ba je pe Oluwa re ba fe, awon ti n be lori ile iba gbagbo, gbogbo won patapata. Nitori naa, se iwo l’o maa je won nipa ni titi won yoo fi di onigbagbo ododo

[100] Emi kan ko le gbagbo afi pelu ase Allahu. O si maa fi iya je awon ti ko se laakaye

[101] So pe: "E woye si nnkan ti n be ninu sanmo ati ile. Awon ayah ati ikilo ko si nii ro ijo alaigbagbo loro

[102] Nitori naa, se won tun n reti (nnkan miiran) ni bi ko se (iparun) iru ti igba awon t’o re koja lo siwaju won. So pe: “E maa reti nigba naa. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.”

[103] Leyin naa, A oo gba awon Ojise Wa ati awon t’o gbagbo la. Bayen ni o se je ojuse Wa lati gba awon onigbagbo ododo la

[104] So pe: “Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa esin mi. Nigba naa, emi ko nii josin fun awon ti e n josin fun leyin Allahu. Sugbon emi yoo maa josin fun Allahu, Eni ti O maa gba emi yin. Won si pa mi ni ase pe ki ng wa ninu awon onigbagbo ododo

[105] (Won tun pa mi lase pe): “Doju re ko esin naa, (ki o je) oluduro-deede-ninu-esin. Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo

[106] Ati pe ma se pe leyin Allahu nnkan ti ko le se o ni anfaani, ti ko si le ko inira ba o. Ti o ba se bee nigba naa, dajudaju iwo ti wa ninu awon alabosi.”

[107] Ti Allahu ba mu inira ba o, ko si eni ti o le mu un kuro afi Oun. Ti O ba si gbero oore kan pelu re, ko si eni ti o le da oore Re pada. O n soore fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. Oun ni Alaforijin, Asake-orun

[108] So pe: "Eyin eniyan, dajudaju ododo ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, enikeni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni ti o ba si sina, o sina fun emi ara re. Emi si ko ni oluso fun yin

[109] Tele ohun ti A fi ranse si o ninu imisi. Ki o si se suuru titi Allahu yoo fi se idajo. Oun si loore julo ninu awon oludajo

Húdù

Surah 11

[1] ’Alif lam ro. (Eyi ni) Tira ti won ti to awon ayah inu re ni atogun rege, leyin naa won salaye re yekeyeke lati odo Ologbon, Alamotan

[2] (A ti salaye re) pe e ma josin fun kini kan afi Allahu. Dajudaju emi ni olukilo ati oniroo idunnu fun yin lati odo Re

[3] (A ti salaye re) pe ki e toro aforijin lodo Oluwa yin. Leyin naa, ki e ronu piwada sodo Re. O maa fun yin ni igbadun daadaa titi di gbedeke akoko kan. O maa fun onise-asegbore ni esan ise asegbore re. Ti e ba si peyin da, dajudaju emi n paya iya Ojo nla fun yin

[4] Odo Allahu ni ibupadasi yin. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[5] Gbo, dajudaju awon sobe-selu musulumi n bo ohun ti n be ninu igba-aya won lati le fara pamo fun Allahu. Kiye si i, nigba ti won n yiso won bora, Allahu mo nnkan ti won n fi pamo ati nnkan ti won n safi han re. Dajudaju Oun ni Onimo nipa nnkan ti n be ninu igba-aya eda

[6] Ko si eda abemi kan t’o wa lori ile afi ki arisiki re wa lodo Allahu. O si mo ibugbe re (nile aye) ati ile ti o maa ku si. Gbogbo re ti wa ninu akosile t’o yanju

[7] Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa - Ite ola Re si wa lori omi (siwaju eyi) – nitori ki O le dan yin wo pe, ewo ninu yin l’o dara julo (nibi) ise rere. Ti o ba kuku so pe dajudaju won yoo gbe yin dide leyin iku, dajudaju awon t’o sai gbagbo yoo wi pe: “Eyi ko je kini kan bi ko se idan ponnbele.”

[8] Dajudaju ti A ba sun iya siwaju fun won di igba t’o ni onka, dajudaju won yoo wi pe: “Ki l’o n da a duro na?” Gbo, ni ojo ti iya yoo de ba won, ko nii se e gbe kuro fun won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si maa diya t’o maa yi won po

[9] Ati pe dajudaju ti A ba fi ike kan to eniyan lenu wo lati odo Wa, leyin naa, ti A ba gba a kuro lowo re, dajudaju o maa di olusoretinu, alaimoore

[10] Dajudaju ti A ba si fun un ni idera towo leyin inira t’o fowo ba a, dajudaju o maa wi pe: “Awon aburu ti kuro lodo mi.” Dajudaju o maa di alayoporo, onifaari

[11] Ayafi awon t’o ba se suuru, ti won si se awon ise rere. Awon wonyen, ti won ni aforijin ati esan t’o tobi

[12] Boya o fe gbe apa kan ohun ti A fi ranse si o sile, ki irewesi si ba okan re nipa re (ni ti ipaya pe) won n wi pe: "Ki ni ko je ki apoti-oro kan sokale fun un, tabi ki molaika kan ba a wa?” Olukilo ni iwo. Allahu si ni Oluso lori gbogbo nnkan

[13] Tabi won n wi pe: “O hun un ni.” So pe: “E mu surah mewaa adahun bi iru re wa, ki e si ke si eni ti e ba le ke si leyin Allahu ti e ba je olododo.”

[14] Nigba naa ti won ko ba da yin lohun, ki e mo pe dajudaju won so (al-Ƙur’an) kale pelu imo Allahu. Ati pe ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, se eyin yoo di musulumi

[15] Enikeni ti o ba n fe isemi aye ati oso re, A oo san won ni esan ise won nile aye. A o si nii din kini kan ku fun won nile aye

[16] Awon wonyen ni awon ti ko nii si kini kan fun mo ni Ojo Ikeyin afi Ina. Nnkan ti won gbele aye si maa baje. Ofo si ni ohun ti won n se nise

[17] Nje eni t’o n be lori eri t’o yanju lati odo Oluwa re (iyen, Anabi s.a.w.), ti olujerii kan (iyen, molaika Jibril) si n ke al-Ƙur’an (fun un) lati odo Allahu, ti tira (Anabi) Musa si ti wa siwaju re, ti o je tira ti won n tele, o si je ike (fun won), (nje Anabi yii jo olusina bi?) Awon (musulumi) wonyi ni won si gba a gbo ni ododo. Enikeni t’o ba sai gba a gbo ninu awon ijo (nasara, yehudi ati osebo), nigba naa Ina ni adehun re. Nitori naa, ma se wa ninu iyemeji nipa al-Ƙur’an. Dajudaju ododo ni lati odo Oluwa re, sugbon opolopo eniyan ni ko gbagbo

[18] Ati pe ta ni o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu? Awon wonyen ni won yoo ko wa siwaju Oluwa won. Awon elerii (iyen, awon molaika) yo si maa so pe: "Awon wonyi ni awon t’o paro mo Oluwa won." Gbo, ibi dandan Allahu ki o maa ba awon alabosi

[19] awon t’o n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, ti won si n fe ko wo. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin

[20] Awon wonyen ko le mori bo ninu iya Allahu lori ile ati pe ko si alaabo kan fun won leyin Allahu. A o si se adipele iya fun won. Won ko le gbo. Ati pe won ki i riran (ri ododo)

[21] Awon wonyen ni awon t’o se emi ara won lofo. Ohun ti won si n da ni adapa iro ti di ofo mo won lowo

[22] Ni ti ododo, dajudaju awon gan-an ni eni ofo julo ni Ojo Ikeyin

[23] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won si dunni mo ironupiwada sodo Oluwa won, awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re

[24] Afiwe ijo mejeeji da bi afoju ati aditi pelu oluriran ati olugboro. Nje awon mejeeji dogba ni afiwe bi? Se e o nii lo iranti ni

[25] A si kuku ti ran (Anabi) Nuh si ijo re (lati so pe) dajudaju olukilo ponnbele ni mo je fun yin

[26] (Mo n kilo) pe ki e ma se josin fun eni kan afi Allahu. Dajudaju emi n paya iya ojo eleta-elero fun yin

[27] Awon asiwaju t’o sai gbagbo ninu ijo re si wi pe: "Awa ko mo o si eni kan tayo abara bi iru wa. Awa ko si mo awon t’o tele o si eni kan kan tayo awon eni yepere ninu wa, olopolo bin-intin. Ati pe awa ko ri yin si eni t’o fi ona kan kan ni ajulo lori wa, sugbon a ka yin kun opuro

[28] (Anabi Nuh) so pe: "Eyin ijo mi, e so fun mi, ti mo ba wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, ti O si fun mi ni ike kan lati odo Re, ti won ko si je ki e riran ri (ododo naa), nje a oo fi dandan mu yin bi, nigba ti emi yin ko o

[29] Eyin ijo mi, emi ko bi yin leere owo kan lori re. Ko si esan mi nibi kan bi ko se lodo Allahu. Emi ko si nii le awon t’o gbagbo danu. Dajudaju won yoo pade Oluwa won, sugbon dajudaju emi n ri yin si ijo alaimokan

[30] Eyin ijo mi, ta ni o maa ran mi lowo nibi (iya) Allahu ti mo ba le won danu? Se e o nii lo iranti ni

[31] Emi ko si so fun yin pe awon ile-owo Allahu n be lodo mi. Emi ko si mo ikoko. Emi ko si so pe molaika ni mi. Emi ko si le so fun awon ti e n foju bin-intin wo pe, Allahu ko nii soore fun won. Allahu nimo julo nipa nnkan t’o n be ninu emi won. Bi bee ko nigba naa, dajudaju mo ti wa ninu awon alabosi

[32] Won wi pe: "Iwo Nuh, O ma kuku ti ja wa niyan. O si se ariyanjiyan pupo pelu wa. Nitori naa, mu ohun ti o se ni ileri fun wa wa ti o ba wa lara awon olododo

[33] (Anabi Nuh) so pe: "Allahu l’O maa mu un wa ba yin ti O ba fe. Eyin ko si nii mori bo

[34] Imoran mi ko si le se yin ni anfaani ti mo ba fe gba yin nimoran, ti Allahu ba fe pa yin run. Oun ni Oluwa yin. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

[35] Tabi won n wi pe: "O hun un ni." So pe: "Ti mo ba hun un, emi ni mo ni ese mi. Emi si yowo yose ninu ohun ti e n da lese

[36] A si fi imisi ranse si (Anabi) Nuh pe dajudaju ko si eni kan ti o maa gbagbo mo ninu ijo re afi eni t’o ti gbagbo tele. Nitori naa, ma se banuje nipa nnkan ti won n se nise

[37] Ki o si kan oko oju-omi naa loju Wa (bayii) pelu imisi Wa. Ma si se ba Mi soro nipa awon t’o sabosi. Dajudaju A maa te won ri ni

[38] O si n kan oko oju-omi naa lo. Nigbakigba ti awon otokulu ninu ijo re ba koja lodo re, won yo si maa fi se yeye. (Anabi Nuh) si so pe: "Ti e ba fi wa se yeye, dajudaju awa naa yoo fi yin se yeye gege bi e se n fi wa se yeye

[39] Nitori naa, laipe e maa mo eni ti iya maa de ba, ti o maa yepere re, ti iya gbere si maa ko le lori

[40] (Bayii ni oro wa) titi di igba ti ase Wa de, omi si seyo gbuu lati oju-aro (ti won ti n se buredi). A so pe: "Ko gbogbo nnkan ni orisi meji tako-tabo ati ara ile re sinu oko oju-omi - ayafi eni ti oro naa ti ko le lori (fun iparun) - ati enikeni t’o gbagbo ni ododo. Ko si si eni t’o ni igbagbo ododo pelu re afi awon die

[41] (Anabi Nuh) so pe: "E wo inu oko oju-omi naa. O maa rin, o si maa gunle ni oruko Allahu. Dajudaju Oluwa mi ni Alaforijin, Asake-orun

[42] O si n gbe won lo ninu igbi omi t’o da bi apata. (Anabi Nuh) si ke si omokunrin re, ti o ti yara re soto: "Omokunrin mi, gun oko oju-omi pelu wa. Ma si se wa pelu awon alaigbagbo

[43] O wi pe: “Emi yoo fori pamo sibi apata kan ti o maa la mi nibi omi.” (Anabi Nuh) so pe: "Ko si alaabo kan ni oni nibi ase Allahu afi eni ti Allahu ba saanu." Igbi omi si la awon mejeeji laaarin. O si di ara awon oluteri sinu omi

[44] A so pe: "Ile, fa omi re mu. Sanmo, dawo (ojo) duro." Won si din omi ku. Oro iparun won si wa si imuse. (Oko oju-omi) si gunle sori apata Judi. A si so pe: “Ijinna rere si ike Allahu ni ti ijo alabosi.”

[45] (Anabi) Nuh pe Oluwa re, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju omo mi wa ninu ara ile mi. Ati pe dajudaju adehun Re, ododo ni. Iwo l’O si mo ejo da julo ninu awon adajo

[46] Allahu so pe: “Nuh, dajudaju ko si ninu ara ile re (ni ti esin). Dajudaju ise ti ko dara ni. Nitori naa, o o gbodo bi Mi leere nnkan ti o o ni imo nipa re. Dajudaju Emi n kilo fun o nitori ki o ma baa di ara awon alaimokan.”

[47] O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n sa di O nibi ki ng bi O leere nnkan ti emi ko ni imo re. Ti O o ba forijin mi, ki O si saanu mi, emi yoo wa lara awon eni ofo

[48] A so pe: "Nuh, sokale pelu alaafia lati odo Wa. Ati pe ki ibukun wa pelu re ati awon ijo ninu awon t’o n be pelu re. Awon ijo kan (tun n bo), ti A oo fun won ni igbadun (oore aye). Leyin naa, iya eleta-elero yo si fowo ba won lati odo Wa

[49] Iwonyi wa ninu iro ikoko ti A n fi (imisi re) ranse si o. Iwo ati ijo re ko nimo re siwaju eyi (ti A sokale fun o). Nitori naa, se suuru. Dajudaju ikangun rere wa fun awon oluberu (Allahu)

[50] (Eni ti A ran nise) si iran ‘Ad ni arakunrin won, (Anabi) Hud. O so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. Eyin ko si je kini kan bi ko se aladaapa iro

[51] Eyin ijo mi, emi ko bi yin leere owo-oya kan lori re. Ko si esan mi nibi kan bi ko se lodo Eni ti O pile iseda mi. Se e o nii se laakaye ni

[52] Eyin ijo mi, e toro aforijin lodo Oluwa Eledaa yin, leyin naa, ki e ronu piwada sodo Re nitori ki O le rojo fun yin ni pupo lati sanmo ati nitori ki O le se alekun agbara kun agbara yin. E ma se peyin da lati di elese (sinu aigbagbo)

[53] Won wi pe: "Hud, o o mu eri kan t’o yanju wa fun wa. Awa ko si nii gbe awon orisa wa ju sile nitori oro (enu) re. Ati pe awa ko ni igbagbo ninu re

[54] nkan ti a n so fun o ni pe awon kan ninu awon orisa wa ti fi inira kan o (l’o fi n so isokuso nipa won)." O so pe: "Dajudaju emi n fi Allahu se Elerii ati pe ki eyin naa jerii pe dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo

[55] dipo jijosin fun Allahu. Nitori naa, e parapo dete si mi. Leyin naa, ki e ma se lo mi lara

[56] Dajudaju emi gbarale Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin. Ko si eda kan afi ki (o je pe) Oun l’O maa fi aaso ori re mu un. Dajudaju Oluwa mi wa lori ona taara

[57] Nitori naa, ti e ba peyin da (nibi ododo), mo kuku ti fi ohun ti Won fi ran mi nise jise fun yin, Oluwa mi yo si fi ijo kan t’o maa yato si eyin ropo yin. E o si le ko inira kan kan ba A. Dajudaju Oluwa mi ni Oluso lori gbogbo nnkan

[58] Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Hud ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa; A gba won la ninu iya t’o nipon

[59] Iran ‘Ad niyen; won tako awon ayah Oluwa won. Won si yapa awon Ojise won. Won si tele ase gbogbo awon alafojudi alatako-ododo

[60] A fi egun tele won nile aye yii ati ni Ojo Ajinde. Gbo, dajudaju iran ‘Ad sai gbagbo ninu Oluwa won. Kiye si i, ijinna rere si ike n be fun iran ‘Ad, ijo (Anabi) Hud

[61] (Eni ti A ran nise) si iran Thamud ni arakunrin won, (Anabi) Solih. O so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. Oun l’O pile iseda yin lati ara (erupe) ile. O si fun yin ni isemi lo lori re. Nitori naa, e toro aforijin lodo Re. Leyin naa, e ronu piwada sodo Re. Dajudaju Oluwa mi ni Olusunmo, Olujepe (eda).”

[62] Won wi pe: “Solih, o ti wa laaarin wa ni eni ti a ni ireti si (pe o maa sanjo) siwaju (oro ti o so) yii. Se o maa ko fun wa lati josin fun ohun ti awon baba wa n josin fun ni? Dajudaju awa ma wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa nnkan ti o n pe wa si.”

[63] O so pe: "Eyin ijo mi, e so fun mi, ti o ba je pe emi wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, ti ike kan si de ba mi lati odo Re, ta ni eni ti o maa ran mi lowo ninu (iya) Allahu ti mo ba yapa Re? Ko si kini kan ti e le fi se alekun re fun mi yato si iparun

[64] Eyin ijo mi, eyi ni abo rakunmi Allahu. O je ami fun yin. Nitori naa, e fi sile, ki o maa je kiri lori ile Allahu. E ma se fi inira kan an nitori ki iya t’o sunmo ma baa je yin

[65] Won si gun un pa. O so pe: “E jegbadun ninu ile yin fun ojo meta (ki iya yin to de). Iyen ni adehun ti ki i se iro.”

[66] Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Solih ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa. (A tun gba won la) ninu abuku ojo yen. Dajudaju Oluwa Re, Oun ni Alagbara, Olubori (eda)

[67] Ohun igbe lile gba awon t’o sabosi mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won

[68] Afi bi eni pe won ko gbenu ilu naa ri. Gbo, dajudaju iran Thamud sai gbagbo ninu Oluwa won. Kiye si i, ijinna rere si ike n be fun ijo Thamud

[69] Dajudaju awon Ojise Wa ti mu iro idunnu wa ba (Anabi) ’Ibrohim. Won so pe: “Alaafia (fun o).” O so pe: “Alaafia (fun yin).” Ko si pe rara t’o fi gbe omo maalu ayangbe wa

[70] Nigba ti o ri owo won pe ko kan ounje, o f’oju odi wo (aijeun) won. Iberu won si wa ninu okan re. Won so pe: “Ma se beru. Dajudaju awon eniyan (Anabi) Lut ni Won ran awa si.”

[71] Iyawo re wa ni iduro, o rerin-in. A si fun un ni iro idunnu (pe o maa bi) ’Ishaƙ. Ati pe leyin ’Ishaƙ ni Ya‘ƙub (iyen, omoomo)

[72] O so pe: “Hen-en! Se pe mo maa bimo? Arugbobinrin ni mi, baale mi yii si ti dagbalagba! Dajudaju eyi ni nnkan iyanu.”

[73] Won so pe: “Se o maa seemo nipa ase Allahu ni? Ike Allahu ati ibukun Re ki o maa be fun yin, eyin ara ile (yii). Dajudaju Allahu ni Olope, Eleyin.”

[74] Nigba ti iberu kuro lara (Anabi) ’Ibrohim, ti iro idunnu si ti de ba a, o si n parowa fun (awon Ojise) Wa nipa ijo (Anabi) Lut

[75] Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim ni alafarada, oluraworase, oluronupiwada

[76] (Anabi) ’Ibrohim, seri kuro nibi eyi. Dajudaju ase Oluwa re ti de. Ati pe dajudaju awon ni iya ti ko se e da pada yoo de ba

[77] Nigba ti awon Ojise Wa de ba (Anabi) Lut, o banuje nitori won. Agbara re ko si ka oro won mo. O si so pe: “Eyi ni ojo t’o le pupo.”

[78] Awon eniyan re wa ba a, ti won n sare gbon wa si odo re. Teletele won si ti n se ise aburu (bii ibalopo laaarin okunrin ati okunrin). O so pe: "Eyin eniyan mi, awon wonyen ni omobinrin mi, won mo julo fun yin (lati fi saya). Nitori naa, e beru Allahu. Ki e si ma se doju ti mi lodo alejo mi. Se ko si okunrin olumona kan ninu yin ni

[79] Won wi pe: “Iwo kuku ti mo pe awa ko letoo kan si awon omobinrin re. O si ti mo nnkan ti a n fe.”

[80] O so pe: "Ti o ba je pe dajudaju agbara kan wa fun mi lori yin ni, tabi (pe) mo le darapo mo ebi kan t’o lagbara ni, (emi iba di yin lowo nibi aburu yin)

[81] (Awon molaika) so pe: “(Anabi) Lut, dajudaju Ojise Oluwa re ni awa. Won ko le (fowo aburu) kan o. Nitori naa, mu awon ara ile re jade ni abala kan ninu oru. Ki eni kan ninu yin ma si se siju weyin wo, afi iyawo re, dajudaju adanwo re ni ohun ti o maa sele si won. Dajudaju akoko (adanwo) won ni owuro. Se owuro ko sunmo ni

[82] Nigba ti ase Wa de, A so oke ilu won di isale re (ilu won si doju bole). A tun ro ojo okuta amo (sisun) le won lori ni telentele

[83] (Awon okuta naa) ti ni ami (oruko eni kookan won lara) lati odo Oluwa re. Won ko si jinna si awon alabosi

[84] (Eni ti A ran nise) si iran Modyan ni arakunrin won, (Anabi) Sua‘eb. O so pe: "Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. E ma se din kongo ati osuwon ku. Mo ri yin pelu daadaa (ti Allahu se fun yin). Dajudaju emi si n paya iya ojo kan ti o maa yi yin po

[85] Eyin ijo mi, e won kongo ati osuwon kun ni dogbadogba. E ma se din nnkan awon eniyan ku. Ki e si ma se bale je ni ti obileje

[86] Ohun ti Allahu ba seku fun yin (ninu halal) loore julo fun yin ti e ba je onigbagbo ododo. Emi ki i si se oluso lori yin

[87] Won wi pe: "Su‘aeb, se irun re l’o n pa o lase pe ki a gbe ohun ti awon baba wa n josin fun ju sile, tabi (irun re lo n ko fun wa) lati se ohun ti a ba fe ninu dukia wa? Dajudaju iwo ma ni alafarada, olumona (loju ara re niyen)

[88] O so pe: “Eyin ijo mi, e so fun mi, ti o ba je pe mo wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, ti (Oluwa mi) si fun mi ni arisiki lati odo Re ni arisiki t’o dara (se ki ng maa je haramu pelu re ni?). Emi ko si fe yapa yin nipa nnkan ti mo n ko fun yin (iyen ni pe, emi naa n lo ohun ti mo n so fun yin). Ko si ohun ti mo fe bi ko se atunse pelu bi mo se lagbara mo. Ko si konge imona kan fun mi bi ko se pelu (iyonda) Allahu. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni mo maa seri si (fun ironupiwada)

[89] Eyin ijo mi, e ma se je ki (bi) e se n yapa mi mu yin lugbadi iru ohun ti o sele si ijo (Anabi) Nuh tabi ijo (Anabi) Hud tabi ijo (Anabi) Solih. Ijo (Anabi) Lut ko si jinna si yin

[90] Ki e si toro aforijin lodo Oluwa yin. Leyin naa, ki e ronu piwada sodo Re. Dajudaju Oluwa mi ni Alaaanu, Ololufe (eda).”

[91] Won wi pe: "Su‘aeb, a o gbo agboye opolopo ninu ohun ti o n so. Dajudaju awa si n ri o ni ole laaarin wa. Ti ko ba je pe nitori ti ebi re ni, a iba ti ku o loko pa; iwo ko si nii lagbara kan lori wa

[92] O so pe: “Eyin ijo mi, se ebi mi lo lagbara loju yin ju Allahu? E si so Allahu di Eni ti e koyin kopako si! Dajudaju Oluwa mi ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[93] Eyin ijo mi, e maa se bi e ti fe ninu esin yin, dajudaju emi yoo maa ba esin mi lo. Laipe eyin yoo mo eni ti iya maa de ba, ti o maa yepere re, (eyin yo si mo) ta ni opuro. Nitori naa, e maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ti mo n reti (ikangun oro yin).”

[94] Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Su‘aeb ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa. Ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won

[95] Afi bi eni pe won ko gbe inu ilu naa ri. Gbo, ijinna si ike n be fun iran Modyan gege bi iran Thamud se jinna si ike

[96] Dajudaju A fi awon ami Wa ati eri ponnbele ran (Anabi) Musa

[97] si Fir‘aon ati awon ijoye re. Awon eniyan si tele ase Fir‘aon. Ase Fir‘aon ko si je imona

[98] O maa siwaju ijo re ni Ojo Ajinde. O si maa ko won wo inu Ina. Wiwo Ina naa si buru

[99] A fi egun tele won nile aye yii ati ni Ojo Ajinde. Ebun egun ti A fun won si buru

[100] Iyen wa ninu awon iro ilu ti A n so itan re fun o. O wa ninu awon ilu naa eyi ti o si n je ilu ati eyi ti o ti pare

[101] A o sabosi si won, sugbon won sabosi si emi ara won. Nitori naa, awon orisa won, ti won n pe leyin Allahu, ko ro won loro nigba ti ase Oluwa re de. Won ko se alekun kan fun won bi ko se iparun

[102] Bayen ni igbamu Oluwa re. Nigba ti O ba gba awon ilu alabosi mu, dajudaju O maa gba a mu pelu iya eleta-elero t’o le

[103] Dajudaju ami wa ninu iyen fun enikeni t’o paya iya Ojo Ikeyin. Iyen ni ojo ti A oo ko awon eniyan jo. Ati pe iyen ni ojo ti gbogbo eda yoo foju ri

[104] A o si fi fale bi ko se di akoko t’o lojo

[105] Ni ojo t’o ba de, emi kan ko nii soro afi pelu iyonda Allahu. Olori buruku ati olori ire yo si wa ninu awon eda (ni ojo naa)

[106] Ni ti awon t’o ba sori buruku, won yoo wa ninu Ina. Won yoo maa gbin too, won yo si maa ke too

[107] Olusegbere ni won ninu re ni odiwon igba ti awon sanmo ati ile fi n be, afi ohun ti Oluwa re ba fe . Dajudaju Oluwa ni Aseyi-o-wuu

[108] Ni ti awon ti A ba se ni olori-ire, won maa wa ninu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re ni odiwon igba ti awon sanmo ati ile fi n be,1 afi ohun ti Oluwa re ba fe.2 (Ogba Idera je) ore ailopin

[109] Nitori naa, ma se wa ninu royiroyi nipa ohun ti awon wonyi n josin fun. Won ko josin fun kini kan bi ko se bi awon baba won naa se n josin (fun awon orisa) ni isaaju. Dajudaju Awa yoo san won ni esan ipin (iya) won lai nii ku sibi kan

[110] A kuku fun (Anabi) Musa ni Tira. Won si yapa enu nipa re. Ati pe ti ki i ba se oro kan ti o ti gbawaju lati odo Oluwa re ni, Awa iba ti sedajo laaarin won. Dajudaju won kuku wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa al-Ƙur’an

[111] Dajudaju eni kookan won ni Oluwa re yoo san ni esan ise won. Dajudaju Oun ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise

[112] Duro sinsin gege bi A se pa iwo ati enikeni ti o ba ronu piwada pelu re lase. E ma se tayo enu-ala. Dajudaju Oun ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[113] E ma se te sodo awon t’o sabosi nitori ki Ina ma baa fowo ba yin. Ko si nii si awon alaabo fun yin leyin Allahu. Leyin naa, A o nii ran yin lowo

[114] Kirun ni ibere ati ipari osan (iyen, irun Subh, Thuhr ati ‘Asr) ati ni ibere oru (iyen, irun Mogrib ati ‘Isa’). Dajudaju awon ise rere n pa awon ise aburu re. Iyen ni iranti fun awon oluranti (Allahu)

[115] Se suuru. Dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare

[116] Ki o si je pe awon onilaakaye kan wa ninu awon iran t’o siwaju yin (ninu awon ti A pare) ki won maa ko ibaje lori ile – afi eniyan die lara awon ti A gbala ninu won. - Awon t’o sabosi si tele nnkan ti A fi se gbedemuke fun won. Won si je elese

[117] Oluwa re ko nii pa awon ilu run lona abosi, nigba ti awon eniyan re ba je olusatun-unse

[118] Ti o ba je pe Oluwa re ba fe, iba se awon eniyan ni ijo elesin kan soso. (Amo) won ko nii ye yapa enu (si ’Islam)

[119] afi eni ti Oluwa re ba ke. Nitori iyen l’O fi seda won. Oro Oluwa re si ti se (bayii pe): “Dajudaju Emi yoo mu ninu awon alujannu ati eniyan ni apapo kunnu ina Jahanamo.”

[120] Gbogbo (nnkan ti) A n so itan re fun o ninu awon iro awon Ojise ni eyi ti A fi n fi o lokan bale. Ododo tun de ba o ninu (surah) yii. Waasi ati iranti tun ni fun awon onigbagbo ododo

[121] Ki o si so fun awon ti ko gbagbo pe: "E maa se bi e ti fe ninu esin yin. Dajudaju awa naa yoo maa ba esin wa lo

[122] E maa reti, dajudaju Awa naa n reti

[123] Ti Allahu ni ikoko awon sanmo ati ile. Odo Re si ni won maa seri gbogbo oro eda pada si. Nitori naa, josin fun Un, ki o si gbarale E. Oluwa re ki i si se onigbagbera nipa nnkan ti e n se nise

Yúsúfù

Surah 12

[1] ’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira t’o yanju oro eda

[2] Dajudaju Awa so o kale ni nnkan kike ni ede Larubawa nitori ki e le se laakaye

[3] Awa n so itan t’o dara julo fun o pelu ohun ti A fi ranse si o (ninu imisi) al-Ƙur’an yii, bi o tile je pe siwaju imisi naa iwo wa lara awon ti ko nimo (nipa re)

[4] (Ranti) nigba ti (Anabi) Yusuf so fun baba re pe: “Baba mi, dajudaju emi (lalaa) ri awon irawo mokanla, oorun ati osupa. Mo ri won ti won fori kanle fun mi.”

[5] O so pe: "Omo mi, ma se ro ala re fun awon obakan re nitori ki won ma baa dete si o. Dajudaju Esu ni ota ponnbele fun eniyan

[6] Bayen ni Oluwa re yoo se sa o lesa. O maa fi itumo ala mo o. O si maa pe idera Re fun iwo ati awon ebi Ya‘ƙub, gege bi O se pe e siwaju fun awon baba re mejeeji, (Anabi) ’Ibrohim ati ’Ishaƙ. Dajudaju Oluwa re ni Onimo, Ologbon

[7] Dajudaju awon ami (ariwoye) n be fun awon onibeeere nipa (itan Anabi) Yusuf ati awon obakan re

[8] (Ranti) nigba ti won so pe: "Dajudaju Yusuf ati omo-iya re ni baba wa nifee si ju awa. Opo eniyan si ni awa. Dajudaju baba wa ma ti wa ninu asise ponnbele

[9] E pa Yusuf tabi ki e lo gbe e junu si ile (miiran) nitori ki baba yin le roju gbo tiyin. E si maa di eniyan rere leyin re

[10] Onsoro kan ninu won so pe: "E ma se pa Yusuf. Ti o ba je pe e sa fe wa nnkan se (si oro re), e gbe e ju sinu isaleesale kannga nitori ki apa kan ninu awon onirin-ajo le baa he e lo

[11] Won so pe: “Baba wa, ki ni ko mu o fi okan tan wa lori Yusuf. Dajudaju awa si maa je olutoju re

[12] Je ki o ba wa lo ni ola nitori ki o le dara ya, ki o si le sere. Ati pe dajudaju awa ni oluso fun un.”

[13] O so pe: “Dajudaju o maa ba mi ninu je pe ki e mu u lo. Mo si n paya ki ikoko ma lo pa a je nigba ti eyin ba gbagbe re (sibi kan).”

[14] Won so pe: “Ti ikoko ba fi pa a je, opo eniyan si ni wa, dajudaju awa nigba naa ni eni ofo.”

[15] Nigba ti won mu un lo tan, won panupo pe ki awon ju u si isaleesale kannga. A si fi imisi ranse si Yusuf pe: “Dajudaju iwo yoo fun won ni iro nipa oro won yii nigba ti won ko nii fura.”

[16] Won de ba baba won ni asale, ti won n sunkun

[17] Won so pe: “Baba wa, awa lo dije ere sisa. A si fi Yusuf sile sibi awon eru wa. Nigba naa ni ikoko pa a je. Iwo ko si nii gba wa gbo, awa ibaa je olododo.”

[18] Won de pelu eje iro lara ewu re. (Anabi Ya‘ƙub) so pe: "Rara o, emi yin l’o se oran kan losoo fun yin. Nitori naa, suuru abiyi (loro mi kan). Allahu ni Oluranlowo lori ohun ti e n royin

[19] Awon onirin-ajo kan si de. Won ran aponmi won (ni omi). O si ju doro re sinu kannga. (Yusuf si diro mo okun doro bo sita. Aponmi si) so pe: "Ire idunnu re e! Eyi ni omodekunrin." Won si fi pamo fun tita (bi oja). Allahu si ni Onimo nipa ohun ti won n se nise

[20] Won ta a ni edinwo pelu owo diriham t’o niye. Won si je eni t’o mu un bin-intin

[21] Eni ti o ra a ni (ilu) Misro so fun aya re pe: “Se ibugbe re daadaa. O sunmo ki o wulo fun wa tabi ki a fi somo.” Bayen ni A se fi aye gba Yusuf lori ile. Ati pe ki A tun le fi itumo ala mo on. Allahu ni Olubori lori ase Re, sugbon opolopo eniyan ni ko mo

[22] Nigba ti o di gende tan, A fun un ni ogbon ijinle ati imo. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan rere

[23] Obinrin ti Yusuf wa ninu ile re si jireebe fun ere ife lodo re. O si ti gbogbo ilekun pa. O so pe: “Sunmo mi.” (Yusuf) so pe: “Mo sadi Allahu. Dajudaju oko re ni oga mi. O si se ibugbe mi daadaa. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”

[24] (Obinrin naa) kuku gbero ere ife si i. Oun naa gbero re, Ti ki i ba se pe o ri eri Oluwa re (pe haramu ni sina, iba sunmo on). Bayen ni (oro naa ri) nitori ki A le seri aburu ati sina sise kuro lodo re. Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon eni esa

[25] Awon mejeeji sare lo sibi ilekun. (Obinrin yii) si fa ewu (Yusuf) ya leyin. Awon mejeeji si ba oga re lenu ona. (Obinrin yii) si so pe: “Ki ni esan fun eni ti o gbero aburu si ara ile re bi ko se pe ki a so o sinu ogba ewon tabi iya eleta-elero.”

[26] (Yusuf) so pe: “Oun l’o jireebe fun ere ife lodo mi.” Elerii kan ninu ara ile (obinrin naa) si jerii pe: "Ti o ba je pe won fa ewu re ya niwaju, (obinrin yii) l’o so ododo, (Yusuf) si wa ninu awon opuro

[27] Ti o ba si je pe won fa ewu re ya leyin, (obinrin yii) l’o paro, (Yusuf) si wa ninu awon olododo

[28] Nigba ti (oko) ri ewu re ti won ti fa a ya leyin, o so pe: "Dajudaju ninu ete eyin obinrin ni (eyi). Dajudaju ete yin tobi

[29] Yusuf, seri kuro nibi eyi. Ki iwo (obinrin yii) si toro aforijin fun ese re. Dajudaju iwo wa lara awon alasise

[30] Awon obinrin kan ninu ilu so pe: “Ayaba n jireebe fun ere ife lodo omo odo re; ife kuku ti ko si i lokan. Dajudaju awa n ri oun pe o wa ninu asise ponnbele.”

[31] Nigba ti (ayaba) gbo ete (oro) won (ti won n so nipa re), o ranse si won. O si pese ohun jije ajokooje sile fun won. O fun ikookan won ni obe (ti o maa fi jeun). O si so pe: “Jade si won, (Yusuf).” Nigba ti won ri i, won gbe e tobi (fun ewa ara re). Won si rera won lowo (fun iyanu ewa ara re). Won si wi pe: “Mimo ni fun Allahu! Eyi ki i se abara. Ki ni eyi bi ko se molaika alapon-onle.”

[32] (Ayaba) so pe: “Iyen ni eni ti e bu mi fun. Dajudaju mo jireebe fun ere ife lodo re, o si wa isora. Dajudaju ti ko ba se ohun ti mo n pa lase fun un, won kuku maa fi sinu ogba ewon ni. Dajudaju o si maa wa ninu awon eni yepere.”

[33] (Yusuf) so pe: “Oluwa (Eledaa) mi, ogba ewon ni mo nifee si ju ohun ti won n pe mi si. Ti O o ba si seri ete won kuro lodo mi, emi yoo ko sinu ete won, emi yo si wa lara awon alaimokan.”

[34] Nitori naa, Oluwa re jepe re. O si seri ete won kuro lodo re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Onimo

[35] Leyin igba ti won ti ri awon ami (pe Yusuf ko jebi esun), leyin naa, o han si won pe awon gbodo so o sinu ogba ewon titi di asiko kan na

[36] Awon odokunrin meji kan wo inu ogba ewon pelu re. Okan ninu awon mejeeji so pe: “Emi lalaa ri ara mi pe mo n fun oti.” Eni keji so pe: “Dajudaju emi lalaa ri ara mi pe mo gbe buredi ru sori mi, eye si n je ninu re.” So itumo re fun wa. Dajudaju awa n ri o pe o wa ninu awon eni rere

[37] O so pe: "Ounje ti won n pese fun yin ko ni ti i de ba yin, afi ki emi ti so itumo re fun eyin mejeeji siwaju ki o to de ba yin. Iyen wa ninu nnkan ti Oluwa mi fi mo mi. Dajudaju emi fi esin awon eniyan ti ko gbagbo ninu Allahu sile. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin

[38] Mo si tele esin awon baba mi, (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub. Ko to si wa pe ki a so nnkan kan di akegbe fun Allahu. Iyen wa ninu oore ajulo Allahu lori awa ati lori awon eniyan, sugbon opolopo awon eniyan ki i dupe (fun Allahu)

[39] Eyin akegbe mi mejeeji ninu ewon, se awon oluwa otooto l’o loore julo (lati josin fun) tabi Allahu, Okan soso, Olubori

[40] Ko si ohun kan ti e n josin fun leyin Re bi ko se awon oruko kan ti e so won - eyin ati awon baba yin - Allahu ko so eri kan kale fun un. Idajo (ta ni ijosin to si) ko si fun eni kan afi Allahu. O si ti pase pe e ma josin fun kini kan afi Oun nikan. Iyen ni esin t’o fese rinle, sugbon opolopo awon eniyan ko mo

[41] Eyin akegbe mi mejeeji ninu ewon, ni ti eni kan ninu yin, o maa fun oga re ni oti mu. Ni ti eni keji, won yoo kan an mo igi, eye yo si maa je ninu ori re. Won ti pari oro ti eyin mejeeji n se ibeere nipa re

[42] O si so fun eni ti o ro pe o maa la ninu awon mejeeji pe: “Ranti mi lodo oga re.” Esu si mu (Yusuf) gbagbe iranti Oluwa re (nipa wiwa iranlowo sodo oga re). Nitori naa, o wa ninu ogba ewon fun awon odun die

[43] Oba so pe: “Dajudaju emi lalaa ri maalu meje t’o sanra. Awon maalu meje t’o ru si n je won. (Mo tun lalaa ri) siri meje tutu ati omiran gbigbe. Eyin ijoye, e fun mi ni alaye itumo ala mi ti e ba je eni t’o maa n tumo ala.”

[44] Won so pe: “Awon ala t’o lopo mora won (niyi). Ati pe awa ki i se onimo nipa itumo awon ala.”

[45] Eni ti o la ninu awon (elewon) mejeeji so pe, - o ranti (Yusuf) leyin igba pipe -: “Emi yoo fun yin ni iro nipa itumo re. Nitori naa, e fi ise ran mi na (ki ng lo se iwadii re).”

[46] Yusuf, iwo olododo, fun wa ni alaye itumo ala (yii): maalu meje t’o sanra. Awon maalu meje t’o ru si n je won. Ati siri meje tutu ati omiran gbigbe. (Ki ni itumo re) nitori ki ng le fi abo sodo awon eniyan ati nitori ki won le mo (itumo re)

[47] O so pe: “Eyin yoo gbin nnkan ogbin fun odun meje gbako (gege bi) ise (yin). Ohunkohun ti e ba ko lere oko, ki e fi sile sinu siri re afi die ti e maa je ninu re

[48] Leyin naa, odun meje t’o le (fun oda ojo) yoo de leyin iyen, (awon ara ilu) yo si le je ohun ti e ti (ko lere oko) siwaju afi die ti e maa fi pamo (fun gbigbin)

[49] Leyin naa, odun kan ti Won yoo rojo fun awon eniyan yoo de leyin iyen. Awon eniyan yo si maa fun eso ati wara mu ninu odun naa

[50] Oba so pe: “E mu (Yusuf) wa fun mi.” Nigba ti iranse naa de odo re. (Yusuf) so pe: “Pada sodo oga re, ki o bi i leere pe, ki ni o sele si awon obinrin ti won re owo ara won. Dajudaju Oluwa mi ni Onimo nipa ete won.”

[51] (Oba) so pe: "Ki ni oro tiyin ti je ti e fi jireebe fun ere ife lodo Yusuf?" Won so pe: “Mimo ni fun Allahu. awa ko mo aburu kan mo Yusuf.” Ayaba so pe: “Nisinsin yii ni ododo foju han. Emi ni mo jireebe fun ere ife lodo re. Dajudaju o wa ninu awon olododo.”

[52] (Yusuf so pe): "Iyen nitori ki oba le mo pe dajudaju emi ko janba re ni ikoko. Ati pe dajudaju Allahu ko nii fi imona sibi ete awon onijanba

[53] Emi ko si fora mi mo (nibi erokero); dajudaju emi kuku n pase erokero (fun eda) ni afi eni ti Oluwa mi ba ke. Dajudaju Oluwa mi ni Alaforijin, Asake-orun

[54] Oba so pe: “E mu (Yusuf) wa fun mi. Emi yoo se e ni eni esa lodo mi.” Nigba ti oba ba a soro tan, o so pe: “Lodo wa ni oni dajudaju iwo ni eni pataki, olufokantan.”

[55] (Yusuf) so pe: “Fi mi se alase awon oro ilu, dajudaju alamojuuto onimo ni mi.”

[56] Bayen ni A se fun Yusuf ni ipo ati ibugbe lori ile. O si n gbe ni ibi ti o ba fe. Awa n mu ike Wa ba enikeni ti A ba fe. A o si nii fi esan awon oluse-rere rare

[57] Dajudaju esan ti orun loore julo fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n beru (Allahu)

[58] Awon obakan (Anabi) Yusuf de, won si wole to o. O da won mo. Awon ko si mo on mo

[59] Nigba ti o si ba won di eru ounje won tan, o so pe: "E lo mu obakan yin wa lati odo baba yin. Se e ko ri i pe dajudaju mo n won kongo ni ekun rere ni? Emi si dara julo ninu awon olugbalejo

[60] Ti e o ba si mu un wa, ko si (eru ounje) wiwon fun yin lodo mi. Ki e si ma se sunmo mi

[61] Won so pe: “A maa jireebe fun un lodo baba re. Dajudaju awa maa se bee.”

[62] O si so fun awon omo odo re pe: “E fi owo-oja won sinu eru (ounje) won nitori ki won le mo nigba ti won ba pada de odo ara ile won (pe a ti da a pada fun won), won yo si le pada wa.”

[63] Nigba ti won pada de odo baba won, won so pe: “Baba wa, won ko lati won ounje fun wa. Nitori naa, je ki obakan wa ba wa lo nitori ki a le ri ounje won (wale). Dajudaju awa ni oluso fun un.”

[64] O so pe: “Se ki ng gba yin gbo lori re bi ko se bi mo se gba yin gbo ni isaaju lori omo-iya re? Nitori naa, Allahu loore julo ni Oluso. Oun si ni Alaaanu-julo ninu awon alaaanu.”

[65] Nigba ti won tu eru ounje won, won ri owo-oja won ti won da pada fun won (ninu re). Won so pe: “Baba wa, ki ni a tun n fe? Owo-oja wa niyi ti won ti da pada fun wa. A o si tun fi wa ounje ra fun awon ebi wa. A o si daabo bo obakan wa. A si maa ri alekun eru ounje (ti) rakunmi kan le ru si i. Iwon ounje kekere si niyen (lodo oba).”

[66] O so pe: “Emi ko nii je ki o ba yin lo titi e maa fi se adehun fun mi ni (oruko) Allahu pe dajudaju e maa mu un pada wa ba mi afi ti (awon ota) ba ka yin mo.” Nigba ti won fun un ni adehun won tan, o so pe: “Allahu ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).”

[67] O tun so pe: “Eyin omo mi, e ma se gba enu ona eyo kan wole. E gba enu ona otooto wole. Emi ko le fi nnkan kan ro yin loro lodo Allahu. Ko si idajo (fun eni kan) afi fun Allahu. Oun ni mo gbarale. Oun si ni ki awon olugbarale gbarale.”

[68] Nigba ti won wo (inu ilu) ni awon aye ti baba won pa lase fun won, ko si ro won loro kan kan lodo Allahu bi ko se bukata kan ninu emi (Anabi) Ya‘ƙub ti o muse. Dajudaju onimo ni nipa ohun ti A fi mo on, sugbon opolopo awon eniyan ko mo

[69] Nigba ti won wole ti (Anabi) Yusuf, o mu omo-iya re mora sodo re. O so pe: “Dajudaju emi ni omo-iya re. Nitori naa, ma se banuje nipa ohun ti won n se nise.”

[70] Nigba ti o si ba won di eru won tan, o fi ife-imumi sinu eru omo-iya re. Leyin naa, olupepe kan kede pe: “Eyin ero-rakunmi, dajudaju eyin ni ole.”

[71] Won doju ko won, won so pe: “Ki l’e safeku?”

[72] Won so pe: “A o ri ife oba ni. Eni ti o ba si mu un wa yoo ri eru ounje rakunmi kan gba. Emi si ni oniduroo fun ebun naa.”

[73] Won so pe: “A fi Allahu bura, dajudaju e mo pe a ko wa lati sebaje lori ile. Ati pe awa ki i se ole.”

[74] Won so pe: “Ki ni esan (fun eni ti) o ji i, ti (o ba han pe) eyin je opuro?”

[75] Won so pe: “Esan re; eni ti won ba ba a ninu eru re, oun naa ni esan re. Bayen ni awa naa se n san awon alabosi ni esan.”

[76] O si bere (ayewo) apo won siwaju apo omo-iya re. Leyin naa, o mu un jade lati inu apo omo-iya re. Bayen ni A se fun (Anabi) Yusuf ni ete da. Ko le fi ofin oba mu omo-iya re afi ti Allahu ba fe. A n sagbega fun enikeni ti A ba fe. Onimo wa loke gbogbo onimo

[77] Won so pe: “Ti o ba jale, dajudaju omo-iya re kan ti jale siwaju.” (Anabi) Yusuf si fi oro naa pamo sinu emi re, ko si fi han si won pe (ko ri bee). O (si) so pe: “Ipo tiyin l’o buru julo. Allahu l’O si nimo julo nipa ohun ti e n so.”

[78] Won so pe: "Iwo oba, dajudaju o ni baba arugbo agbalagba kan. Nitori naa, mu eni kan ninu wa dipo re. Dajudaju awa n ri iwo pe o wa ninu awon eni-rere

[79] O so pe: “Mo sadi Allahu pe ki a mu eni kan afi eni ti a ba eru wa lodo re. (Ti a ba mu elomiiran) dajudaju nigba naa alabosi ni wa.”

[80] Nigba ti won soreti nu nipa re, won te soro. Agba (ninu) won so pe: “Se e ko mo pe dajudaju baba yin ti gba adehun yin ti (e se ni oruko) Allahu. Ati pe siwaju (eyi, e ti se) aseeto nipa oro (Anabi) Yusuf. Nitori naa, emi ko nii fi ile (Misro) sile titi baba mi yoo fi yonda fun mi tabi (titi) Allahu yoo fi se idajo fun mi. O si loore julo ninu awon oludajo

[81] E pada sodo baba yin, ki e si so pe: “Baba wa, dajudaju omo re jale. A ko si le jerii (si kini kan) afi ohun ti a ba nimo (nipa) re. Awa ko si je oluso fun ohun ti o pamo (fun wa)

[82] Ki o si bi awon ara ilu ti a wa ninu re ati ero-rakunmi ti a jo dari de leere wo. Dajudaju olododo ma ni wa.”

[83] (Anabi Ya‘ƙub) so pe: “Rara o, emi yin lo se oran kan losoo fun yin. Nitori naa, suuru t’o rewa (loro mi kan bayii). O see se ki Allahu ba mi mu gbogbo won wa. Dajudaju Allahu, Oun ni Onimo, Ologbon.”

[84] O pa won ti, o si so pe: “Ibanuje n be fun mi lori Yusuf!” Oju re mejeeji si funfun wa (ko si riran mo); o si pa ibanuje mora

[85] Won so pe: “A fi Allahu bura, iwo ko ye ranti Yusuf titi o maa fi di yannayanna tabi (titi) o maa fi di ara awon oku.”

[86] O so pe: “Allahu ma ni emi n ro edun okan mi ati ibanuje mi fun. Mo si mo ohun ti e ko mo nipa Allahu

[87] Eyin omo mi, e lo wadii nipa Yusuf ati omo-iya re. E si ma se soreti nu ninu ike Allahu. Dajudaju ko si eni kan ti o maa soreti nu ninu ike Allahu afi ijo alaigbagbo.”

[88] Nigba ti won wole to Yusuf, won so pe: “Iwo oba, inira ti mu awa ati ara ile wa. A si mu owo kan ti ko yanju wa. Nitori naa, won kongo (ounje) naa kun fun wa, ki o si ta wa lore. Dajudaju Allahu yoo san awon olutore ni esan rere.”

[89] O so pe: “Nje e mo ohun ti e se fun Yusuf ati omo-iya re nigba ti eyin je alaimokan.”

[90] Won so pe: “Se dajudaju iwo ni Yusuf?” O so pe: “Emi ni Yusuf. Omo-iya mi si niyi. Dajudaju Allahu ti se idera fun wa. Dajudaju enikeni ti o ba beru (Allahu), ti o si se suuru, dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare.”

[91] Won so pe: “A fi Allahu bura! Dajudaju Allahu ti gbola fun o ju wa lo. Ati pe dajudaju awa ni alasise.”

[92] O so pe: "Ko si ibawi fun yin ni oni. Allahu yoo forijin yin. Oun si ni Alaaanu-julo ninu awon alaaanu

[93] E mu ewu mi yii lo, ki e fi le iwaju baba mi, o maa pada di oluriran. Ki e si ko gbogbo ebi yin wa ba mi

[94] Nigba ti ero-rakunmi naa si pinya (kuro lodo Anabi Yusuf), baba won so pe: “Dajudaju emi n gbo oorun Yusuf ti e o ba nii so pe mo n jaran.”

[95] Won so pe: “A fi Allahu bura! Dajudaju iwo si wa ninu asise re ti atijo (nipa ife Yusuf).”

[96] Nigba ti oniroo-idunnu de, o ju (ewu naa) le e niwaju, o si riran pada. O so pe: “Nje ng ko so fun yin pe dajudaju emi mo ohun ti e ko mo nipa Allahu.”

[97] Won so pe: “Baba wa, toro aforijin ese wa fun wa, dajudaju awa je alasise.”

[98] O so pe: “Laipe mo maa toro aforijin fun yin lodo Oluwa mi. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun.”

[99] Nigba ti won wole to (Anabi) Yusuf, o ko awon obi re mejeeji mora sodo re, o si so pe: “E wo ilu Misro ni olufayabale – ti Allahu ba fe.-”

[100] O gbe awon obi re mejeeji sori ite. Won si doju bole fun un ni oluforikanle-kini. O so pe: “Baba mi, eyi ni itumo ala mi (ti mo la) siwaju. Dajudaju Oluwa mi ti so o di ododo. O si se daadaa fun mi nigba ti O mu mi jade kuro ninu ogba ewon. O tun mu yin wa (ba mi) lati inu oko leyin ti Esu ti ba aarin emi ati awon oba-kan mi je. Dajudaju Oluwa mi ni Alaaanu fun ohun ti O ba fe. Dajudaju Allahu, Oun ni Onimo, Ologbon

[101] Oluwa mi, dajudaju O ti fun mi ni ijoba. O tun fun mi ni imo itumo ala. Olupileda awon sanmo ati ile, Iwo ni Oluranlowo mi ni aye ati ni orun, pa mi sipo musulumi. Ki O si fi mi pelu awon eni rere.”

[102] Iyen wa ninu iro ikoko ti A fi imisi (re) ranse si o. Ati pe iwo ko si lodo won nigba ti won panu po lori oro won, ti won n dete

[103] Iwo ibaa soju kokoro (igbala won), opolopo eniyan ni ko nii gbagbo

[104] Iwo ko si bi won leere owo-oya kan lori re. Ko si je kini kan bi ko se iranti fun gbogbo eda

[105] Ati pe meloo meloo ninu awon ami ti n be ni sanmo ati ni ori ile ti won n re koja lori re, ti won si n gbunri kuro nibe

[106] Opolopo won si ni ko nii gba Allahu gbo ni ododo afi ki won tun maa sebo

[107] Se won faya bale pe ohun ti n bo eda mole ninu iya Allahu ko le de ba awon ni tabi pe Akoko naa ko le ko le awon lori ni ojiji, ti won ko si nii fura

[108] So pe: “Eyi ni oju ona (esin) mi, emi ati awon t’o tele mi si n pepe si (esin) Allahu pelu imo amodaju. Mimo ni fun Allahu. Emi ko si si lara awon osebo.”

[109] A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si ninu awon ara ilu. Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Dajudaju Ile ikeyin loore julo fun awon t’o beru (Allahu). Se e o se laakaye ni

[110] (A ki i je awon eniyan niya) titi di igba ti awon Ojise ba t’o soreti nu (nipa igbagbo won), ti won si mo pe won ti pe awon ni opuro. Aranse Wa yo si de ba won. A si maa gba eni ti A ba fe la. Won ko le da iya Wa pada lori ijo elese

[111] Dajudaju ariwoye wa ninu itan won fun awon onilaakaye. (Al-Ƙur’an) ki i se oro kan ti won n hun, sugbon o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re, o n salaye gbogbo nnkan; o je imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo

Ààrá

Surah 13

[1] ’Alif lam mim ro. Iwonyi ni awon ayah Tira naa. Ati pe ododo ni ohun ti won sokale fun o lati odo Oluwa re, sugbon opolopo awon eniyan ko gbagbo

[2] Allahu ni Eni ti O gbe awon sanmo ga soke lai si awon opo kan (fun un) ti e le foju ri. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. O ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. O n se eto oro (eda). O n se alaye awon ayah nitori ki e le mo amodaju nipa ipade Oluwa yin

[3] Oun ni Eni ti O te ile perese. O si fi awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ati awon odo. Ati pe ninu gbogbo awon eso, O se e ni orisi meji-meji. O n fi oru bo osan loju. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle

[4] O tun wa ninu ile awon abala-abala ile (oniran-anran) t’o wa nitosi ara won ati awon ogba oko ajara, irugbin ati igi dabinu t’o peka ati eyi ti ko peka, ti won n fi omi eyo kan won. (Sibesibe) A se ajulo fun apa kan re lori apa kan nibi jije. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye

[5] Ti o ba seemo, eemo ma ni oro (enu) won (nipa bi won se so pe): “Se nigba ti a ba ti di erupe tan, se nigba naa ni awa yoo tun di eda titun?” Awon wonyen ni awon t’o sai gbagbo ninu Oluwa won. Awon wonyen ni ewon n be lorun won. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re

[6] Won tun n kan o loju pe ki aburu sele siwaju rere. Awon apeere iya kuku ti sele siwaju won. Ati pe dajudaju Oluwa re ni Alaforijin fun awon eniyan lori abosi (owo) won. Dajudaju Oluwa re le nibi iya

[7] Awon t’o sai gbagbo n wi pe: “Ki ni ko je ki Won so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” Olukilo ma ni iwo. Olutosona si wa fun ijo kookan

[8] Allahu mo ohun ti obinrin kookan ni loyun ati ohun ti ile omo yoo fi din ku (ninu ojo ibimo) ati ohun ti o maa fi lekun. Nnkan kookan l’o si ni odiwon lodo Re

[9] (Allahu ni) Onimo-ikoko-ati- gbangba. O tobi, O ga

[10] Bakan naa ni (lodo Allahu), eni ti o fi oro pamo sinu ninu yin ati eni ti o so o sita pelu eni ti o fi oru boju ati eni ti o n rin kiri ni osan

[11] O n be fun eniyan (kookan) awon molaika ti n gbase funra won; won wa niwaju (eniyan) ati leyin re; won n so (ise owo) re pelu ase Allahu. Dajudaju Allahu ko nii se iyipada nnkan t’o n be lodo ijo kan titi won yoo fi yi nnkan t’o n be ninu emi won pada. Nigba ti Allahu ba gbero aburu kan ro ijo kan, ko si eni t’o le da a pada. Ko si si alaabo kan fun won leyin Re

[12] Oun ni Eni t’o n fi monamona han yin ni iberu ati ni ireti (fun yin). O si n seda esujo t’o su dede

[13] Ara n se afomo ati idupe fun Un, awon molaika n se bee fun iberu Re. O n ran ina ara nise. O si n fi kolu eni ti O ba fe. Sibe won n jiyan nipa Allahu. O si le nibi gbigba-eda-mu

[14] TiRe ni ipe ododo. Awon ti won n pe leyin Re, won ko le fi kini kan je pe won afi bi eni ti o tewo re mejeeji (lasan) si omi nitori ki omi le de enu re. Omi ko si le de enu re. Adua awon alaigbagbo ko si je kini kan bi ko se sinu isina

[15] Allahu ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile n fori kanle fun, won fe, won ko, - ooji won (naa n se bee) - ni owuro ati ni asale

[16] So pe: “Ta ni Oluwa awon sanmo ati ile?” So pe: “Allahu ni.” So pe: “Se leyin Re ni e tun mu awon alafeyinti kan, ti won ko ni ikapa oore ati inira fun emi ara won?” So pe: “Se afoju ati oluriran dogba bi? Tabi awon okunkun ati imole dogba? Tabi won yoo fun Allahu ni awon akegbe kan ti awon naa da eda bii ti eda Re, (to bee ge) ti eda fi jora won loju won?” So pe: “Allahu ni Eledaa gbogbo nnkan. Oun si ni Okan soso, Olubori

[17] O n so omi kale lati sanmo. Awon oju-odo si n san pelu odiwon re. Agbara si n gbe ifofo ori-omi lo. Bakan naa, ninu nnkan ti won n yo ninu ina lati fi se nnkan-oso tabi nnkan-elo, ohun naa ni ifofo bi iru re. Bayen ni Allahu se n mu apejuwe ododo ati iro wa. Ni ti ifofo, o maa ba panti lo. Ni ti eyi ti o si maa se eniyan ni anfaani, o maa duro si ori ile. Bayen ni Allahu se n mu apejuwe wa

[18] Ohun rere wa fun awon t’o jepe Oluwa won. Awon ti ko si jepe Re, ti o ba je pe tiwon ni gbogbo nnkan t’o n be lori ile patapata ati iru re pelu re, won iba fi serapada (fun emi ara won nibi Ina). Awon wonyen ni aburu isiro-ise wa fun. Ina Jahanamo ni ibugbe won; ibugbe naa si buru

[19] Nje eni ti o mo pe ododo kuku ni nnkan ti won sokale fun o lati odo Oluwa re da bi eni ti o foju (nipa re)? Awon onilaakaye l’o n lo iranti

[20] (Awon ni) awon t’o n mu adehun Allahu se. Ati pe won ki i tu adehun

[21] (Awon ni) awon t’o n da ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo po. Won n paya Oluwa won. Won si n paya aburu isiro-ise

[22] (Awon ni) awon t’o se suuru lati fi wa Oju rere Oluwa won. Won n kirun. Won n na ninu ohun ti A pese fun won ni ikoko ati ni gbangba. Won si n fi rere ti aburu lo. Awon wonyen ni atubotan Ile rere n be fun

[23] Inu awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo, (awon) ati eni t’o ba se rere ninu awon baba won, awon iyawo won ati awon aromodomo won. Awon molaika yo si maa wole to won lati enu ona kookan

[24] (Won yoo so pe): “Alaafia fun yin nitori ifarada yin.” Atubotan Ile naa si dara

[25] Awon t’o n tu adehun Allahu leyin ti won ti gba adehun Re, ti won n ja ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo, ti won si n se ibaje lori ile; awon wonyen ni egun wa fun. Ati pe Ile (Ina) buruku wa fun won

[26] Allahu n te arisiki sile regede fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun eni ti O ba fe). Won si dunnu si isemi ile aye! Ki si ni isemi aye ni egbe ti orun bi ko se igbadun bin-intin

[27] Awon t’o sai gbagbo n wi pe: “Ki ni ko je ki Won so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Dajudaju Allahu n si eni ti O ba fe lona. O si n fi ona mo eni ti o ba seri sodo Re.”

[28] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti okan won si bale pelu iranti Allahu; e gbo, pelu iranti Allahu ni awon okan maa fi bale

[29] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, ori ire ati abo rere wa fun won

[30] Bayen ni A se ran o nise si ijo kan, (eyi ti) awon ijo kan kuku ti re koja lo siwaju won, nitori ki o le maa ka fun won nnkan ti A fi ranse si o ni imisi. Sibesibe won n sai gbagbo ninu Ajoke-aye. So pe: “Oun ni Oluwa mi. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni abo mi.”

[31] Ti o ba je pe dajudaju Ƙur’an, won fi mu awon apata rin (bo si aye miiran), tabi won fi gele (lati yanu), tabi won fi ba awon oku soro (won si ji dide, won ko nii gbagbo). Amo sa, ti Allahu ni gbogbo ase patapata. Se awon t’o gbagbo ko mo pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba to gbogbo eniyan sona. Ajalu ko si nii ye sele si awon alaigbagbo nitori ohun ti won se nise tabi (ajalu naa ko nii ye) sokale si tosi ile won titi di igba ti adehun Allahu yoo fi de. Dajudaju Allahu ko nii yapa adehun

[32] Dajudaju won ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re. Mo si lo awon t’o sai gbagbo lara. Leyin naa, Mo gba won mu. Nitori naa, bawo ni iya (ti mo fi je won) ti ri (lara won na)

[33] Nje Eni ti O n mojuto emi kookan nipa ise ti o se (da bi eni ti ko le se bee bi? Sibe) e tun ba Allahu wa awon akegbe kan! So pe: “E daruko won na.” Tabi eyin yoo fun (Allahu) ni iro ohun ti ko mo lori ile tabi (eyin yoo pa) iro funfun balau ni? Won kuku ti se ete ni oso fun awon t’o sai gbagbo. Won si seri won kuro loju ona ododo. Enikeni ti Allahu ba si lona, ko si nii si olutosona kan fun un

[34] Iya wa fun won ninu isemi aye (yii). Iya ti Ojo Ikeyin kuku gbopon julo. Ko si nii si alaabo kan fun won lodo Allahu

[35] Apejuwe Ogba Idera ti Won se ni adehun fun awon oluberu Allahu (ni eyi ti) awon odo n san koja nisale re. Eso re ati iboji re yo si maa wa titi laelae. Iyen ni ikangun awon t’o beru (Allahu). Ina si ni ikangun awon alaigbagbo

[36] Awon ti A fun ni Tira n dunnu si ohun ti A sokale fun o. O si wa ninu awon ijo keferi-parapo t’o n se atako si apa kan re. So pe: “Nnkan ti Won pa mi lase re ni pe ki ng josin fun Allahu. Emi ko si gbodo wa akegbe fun Un. Odo Re ni mo n pepe si. Odo Re si ni abo mi.”

[37] Bayen ni A se so o kale ni idajo pelu ede Larubawa. Dajudaju ti o ba fi le tele ife-inu won, leyin nnkan ti o de ba o ninu imo, ko si alaabo ati oluso kan fun o mo lodo Allahu

[38] Dajudaju A ti ran awon Ojise kan nise siwaju re. A si fun won ni awon iyawo ati awon omoomo.1 Ko letoo fun Ojise kan lati mu ami kan wa ayafi pelu iyonda Allahu.2 Gbogbo isele l’o ni akosile

[39] Allahu n pa ohun ti O ba fe re. O si n mu (ohun ti O ba fe) se. Odo Re si ni Tira Ipile wa. bere lati igba ti eda ko ti i maa je eda titi de ikangun eda ninu Ogba Idera tabi ninu Ina. Ninu akosile yii ni Allahu (subhanahu wa ta'ala) ti n yo akosile olodoodun fun awon molaika Re. Nitori naa ohun titun ninu kadara ti n be lowo awon molaika ni agboye “yamhu-llahu mo yasa’”. Bakan naa ki o pada sibi iyapa ase Allahu ki o si ku sinu isina aigbagbo. Onitoun ni eni ti Allahu pa oruko re re ninu imona. Irufe eni yii l’o wa ni abe “yamhu-llahu mo yasa’”. Ni ida keji ewe won yoo yo gbogbo oro ti ko la laada ati iya lo sile awon oro bii “Mo je; mo mu; mo sun; mo ji ati bee bee lo”. Eyi si ni itumo “yamhu-llahu mo yasa’” Won yo si fi awon oro ati ise yooku ti o la laada ati iya lo sile ninu akosile ise eda. Eyi si ni itumo “wa yuthbit”. ti Allahu yoo pa idajo inu won re. Irufe awon ayah bee si l’o wa ni abe “yamhu-llahu mo yasa’”. Ni ida keji ewe awon ayah kan si n be ti Allahu ko nii pa idajo inu won re. Irufe awon ayah bee l’o si wa ni abe “wa yuthbit”. mejeeji ti wa ninu kadara eda ti o wa ninu Tira Laohul-mahfuth. Ati pe ko si eda t’o nimo ewo ninu awon oore aye ati torun l’o maa te eda lowo nipase adua. Eyi je imo ikoko ni abala kan. O tun je ola fun adua sise labala kan nitori pe oore adua oto oore ebun Olohun oto. Nitori naa

[40] O see se ki A fi apa kan eyi ti A se ni ileri fun won han o tabi ki A ti gba emi re (siwaju asiko naa), ise-jije nikan ni ojuse tire, isiro-ise si ni tiWa

[41] Se won ko ri i pe dajudaju A n mu ile dinku (mo awon alaigbagbo lowo) lati awon eti ilu (wo inu ilu nipa fifun awon musulumi ni isegun lori won)? Allahu l’O n se idajo. Ko si eni kan ti o le da idajo Re pada (fun Un). Oun si ni Oluyara nibi isiro-ise

[42] Dajudaju awon t’o siwaju won dete. Ti Allahu si ni gbogbo ete patapata. O mo ohun ti emi kookan n se nise. Ati pe awon alaigbagbo n bo wa mo eni ti atubotan Ile (rere) wa fun

[43] Awon alaigbagbo n wi pe: “Iwo ki i se Ojise.” So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin ati eni ti imo Tira n be lodo re.”

Ibrāhīmù

Surah 14

[1] ’Alif lam ro. (Eyi ni) Tira kan ti A sokale fun o nitori ki o le mu awon eniyan kuro lati inu awon okunkun wa sinu imole pelu iyonda Oluwa won. (Won yo si bo) si ona Alagbara, Olope (ti ope to si)

[2] Allahu, Eni ti O ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Egbe ni fun awon alaigbagbo nibi iya lile

[3] Awon t’o n feran isemi aye ju torun, ti won n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won si n fe ko wo; awon wonyen wa ninu isina t’o jinna

[4] A o ran Ojise kan nise afi pelu ede ijo re1 nitori ki o le salaye (esin) fun won. Nigba naa, Allahu yoo si enikeni ti O ba fe lona. O si maa to enikeni ti O ba fe sona; Oun ni Alagbara, Ologbon

[5] A kuku fi awon ayah Wa ran (Anabi) Musa nise pe: “Mu ijo re kuro lati inu awon okunkun bo sinu imole. Ki o si ran won leti awon idera Allahu (lori won).” Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe

[6] (Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe e ranti ike Allahu lori yin nigba ti O gba yin la lowo awon eniyan Fir‘aon, ti won n fi iya buruku je yin; won n dunnbu awon omokunrin yin, won si n da awon omobinrin yin si. Adanwo nla wa ninu iyen lati odo Oluwa yin

[7] (E ranti) nigba ti Oluwa Eledaa yin so o di mimo (fun yin pe): "Dajudaju ti e ba dupe, Emi yoo salekun fun yin. Dajudaju ti e ba si saimoore, dajudaju iya Mi ma le

[8] (Anabi) Musa so pe: "Ti e ba saimoore, eyin ati awon t’o n be lori ile aye patapata, dajudaju Allahu ni Oloro, Olope

[9] Se iro awon t’o siwaju yin ko ti i de ba yin ni? Ijo (Anabi) Nuh, ijo ‘Ad, ijo Thamud ati awon t’o wa leyin won; ko si eni ti o mo won afi Allahu. Awon Ojise won mu awon eri t’o yanju wa ba won. Nigba naa, won ti owo won bo enu won (ni ti ibinu), won si wi pe: "Dajudaju awa sai gbagbo ninu nnkan ti Won fi ran yin nise. Ati pe dajudaju awa wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa ohun ti e n pe wa si

[10] Awon Ojise won so pe: “Se iyemeji kan n be nibi (bibe) Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile? O n pe yin nitori ki O le fori awon ese yin jin yin ati nitori ki O le lo yin lara di gbedeke akoko kan.” Won wi pe: “Eyin ko je kini kan tayo abara bi iru wa. Eyin si fe se wa lori kuro nibi nnkan ti awon baba wa n josin fun. Nitori naa, e fun wa ni eri ponnbele.”

[11] Awon Ojise won so fun won pe: “Awa ko je kini kan bi ko se abara bi iru yin. Sugbon Allahu n soore fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. Ko si letoo fun wa lati fun yin ni eri kan afi pelu iyonda Allahu. Ati pe, Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

[12] Ki ni o maa se wa ti a o nii gbarale Allahu, O kuku ti fi awon ona wa mo wa. Dajudaju a maa se suuru lori ohun ti e ba fi ko inira ba wa. Allahu si ni ki awon olugbarale gbarale.”

[13] Awon t’o sai gbagbo wi fun awon Ojise won pe: “Dajudaju awa yoo le yin jade kuro lori ile wa tabi ki e kuku pada sinu esin wa.” Nigba naa, Oluwa won fi imisi ranse si won pe: “Dajudaju A maa pa awon alabosi run

[14] Dajudaju A si maa fun yin ni ibugbe lori ile leyin won. ” Iyen wa fun eni ti o ba paya iduro (niwaju) Mi, ti o tun paya ileri Mi

[15] Won si toro aranse (Allahu lori ijo won). Gbogbo alafojudi, olorikunkun si padanu

[16] Ina Jahanamo n be leyin (iparun) re; A o si maa fun un ni omi awoyunweje mu

[17] O maa sare mu un diedie, ko si nii fee le gbe e mi. (Inira) iku yo si maa yo si i ni gbogbo aye, sibe ko nii ku. Iya t’o nipon tun wa fun un leyin re

[18] Afiwe awon t’o sai gbagbo ninu Oluwa won: awon ise won da bi eeru ti ategun fe danu patapata ni ojo iji ategun. Won ko ni agbara kan lori ohun ti won se nise. Iyen ni isina t’o jinna

[19] Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O seda awon sanmo ati ile pelu ododo? Ti O ba fe, O maa ko yin kuro. O si maa mu eda titun wa

[20] Iyen ko si le da Allahu lagara

[21] Gbogbo eda si maa jade sodo Allahu (lojo Ajinde). Nigba naa, awon alailagbara yoo wi fun awon t’o segberaga pe: “Dajudaju awa je omoleyin fun yin, nje eyin le gbe nnkan kan kuro fun wa ninu iya Allahu?” Won yoo wi pe: “Ti o ba je pe Allahu to wa sona ni, awa iba to yin sona. Bakan naa si ni fun wa, yala a kaya soke tabi a satemora (iya); ko si ibusasi kan fun wa.”

[22] Esu yo si wi nigba ti A ba sedajo (eda) tan, pe: “Dajudaju Allahu se adehun fun yin ni adehun ododo. Emi naa se adehun fun yin. Mo si yapa adehun ti mo se fun yin. Emi ko si ni agbara kan lori yin bi ko se pe mo pe yin e si jepe mi. Nitori naa, e ma se bu mi; ara yin ni ki e bu. Emi ko le ran yin lowo (nibi iya), Eyin naa ko si le ran mi lowo (nibi iya). Dajudaju emi ti lodi si ohun ti e fi so mi di akegbe Allahu siwaju.” Dajudaju awon alabosi, iya eleta-elero wa fun won

[23] Won si maa mu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re pelu ase Oluwa won. Ikini won ninu re ni ‘alaafia’

[24] Se o o ri bi Allahu ti sakawe oro daadaa pelu igi daadaa, ti gbongbo re fidi mule sinsin, ti eka re si wa ninu sanmo

[25] to si n so eso (jije) re ni gbogbo igba pelu iyonda Oluwa re? Allahu n fun awon eniyan ni awon akawe nitori ki won le lo iranti

[26] Akawe oro ti ko dara si da bi igi ti ko dara, ti won fa tu lati oke lori ile, ti ko si ni aye kan lori ile

[27] Allahu yoo maa fi awon t’o gbagbo ni ododo rinle pelu oro t’o rinle ninu isemi aye ati ni Ojo Ikeyin. O si maa si awon alabosi lona. Ati pe Allahu n se ohun ti O ba fe

[28] Se o o ri awon t’o yi idera Allahu pada si aigbagbo, ti won si mu ijo won gunle si ile iparun

[29] Ina Jahanamo ni won yoo gunle si; ibugbe naa si buru

[30] Won so (awon kan di) akegbe fun Allahu nitori ki won le seri awon eniyan kuro ninu esin Re. So pe: “E maa gbadun nso, nitori pe dajudaju abo yin ni Ina.”

[31] So fun awon erusin Mi pe ki won kirun, ki won si na ninu ohun ti A pese fun won ni ikoko ati ni gbangba siwaju ki ojo kan to de, ti ko nii si tita-rira kan ati yiyan ore kan ninu re

[32] Allahu ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile. O n so omi kale lati sanmo. O si fi n mu awon eso jade; (o je) arisiki fun yin. O si ro oko oju-omi fun yin ki o le rin loju omi pelu ase Re. O tun ro awon odo fun yin

[33] O ro oorun ati osupa fun yin, ti mejeeji n rin lai sinmi. O tun ro oru ati osan fun yin

[34] Ati pe O n fun yin ninu gbogbo nnkan ti e toro lodo Re. Ti e ba se onka idera Allahu, e ko le ka a tan. Dajudaju eniyan ni alabosi alaimoore

[35] (Ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Oluwa mi, se ilu yii ni ilu ifayabale. Ki O si mu emi ati awon omo mi jinna si jijosin fun awon orisa

[36] Oluwa mi, dajudaju awon orisa ti ko opolopo ninu awon eniyan sonu. Nitori naa, enikeni ti o ba tele mi, dajudaju oun ni eni mi. Enikeni ti o ba si yapa mi, dajudaju Iwo ni Alaforijin, Asake

[37] Oluwa wa, dajudaju emi wa ibugbe fun aromodomo mi si ile afonifoji, ile ti ko ni eso, nitosi Ile Re Olowo. Oluwa wa, nitori ki won le kirun ni. Nitori naa, je ki okan awon eniyan fa sodo won. Ki O si pese awon eso fun won nitori ki won le dupe (fun O)

[38] Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O mo ohun ti a n fi pamo ati ohun ti a n se afihan re. Ko si si kini kan ninu ile ati ninu sanmo t’o pamo fun Allahu

[39] Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O fun mi ni ’Ismo‘il ati ’Ishaƙ nigba ti mo ti darugbo. Dajudaju, Oluwa mi ni Olugbo adua

[40] Oluwa mi, se emi ati ninu aromodomo mi ni olukirun. Oluwa wa, ki O si gba adua mi

[41] Oluwa mi, saforijin fun emi ati awon obi mi mejeeji ati awon onigbagbo ododo ni ojo ti isiro-ise yoo sele

[42] Ma se lero pe Allahu gbagbe nnkan ti awon alabosi n se nise. O kan n lo won lara di ojo kan ti awon oju yoo yo sita rangandan

[43] Won yoo ma sare (lo sibi akojo fun isiro-ise), won yoo gbe ori won soke, ipenpeju won ko si nii pada sodo won, awon okan won yo si pa sofo patapata (fun iberu)

[44] Kilo fun awon eniyan nipa ojo ti iya yoo de ba won, awon t’o sabosi yo si wi pe: “Oluwa wa, lo wa lara fun asiko die si i, a maa jepe Re, a si maa tele awon Ojise.” Se eyin ko ti bura siwaju pe eyin ko nii kuro nile aye ni

[45] E si gbe ninu ibugbe awon t’o sabosi si emi ara won. O si han si yin bi A ti se pelu won. A tun fun yin ni awon akawe

[46] Won kuku ti da ete won, odo Allahu si ni ete won wa, bi o tile je pe (pelu) ete won apata fee le ye lule

[47] Nitori naa, ma se lero pe Allahu yoo yapa adehun Re ti O se fun awon Ojise Re. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olugbesan

[48] Ni ojo ti A maa yi ile aye pada si nnkan miiran. (A maa yi) awon sanmo naa (pada. Awon eda) si maa jade (siwaju) Allahu, Okan soso, Olubori

[49] O si maa ri awon elese ni ojo yen, ti won yoo so won papo mora won sinu sekeseke

[50] Oje Ina ni awon ewu won. Ina yo si bo oju won mole bamubamu

[51] nitori ki Allahu le san esan ohun ti emi kookan se nise. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise

[52] Eyi ni ise-jije fun awon eniyan nitori ki won le fi se ikilo, ki won si le mo pe (Allahu) Oun nikan ni Olohun ti ijosin to si, Okan soso, ati nitori ki awon onilaakaye le lo iranti

Àpáta

Surah 15

[1] ’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira naa ati (awon ayah) al-Ƙur’an t’o n yanju oro eda

[2] O see se ki awon t’o sai gbagbo nifee si pe awon iba si ti je musulumi (nile aye)

[3] Fi won sile, ki won je, ki won gbadun, ki ireti (emi gigun) ko airoju raaye ba won (lati sesin); laipe won maa mo

[4] A ko pa ilu kan run ri afi ki o ni akosile ti A ti mo

[5] Ko si ijo kan (ti o parun) siwaju akoko re (ninu Laohul-Mahfuuth); won ko si nii sun un siwaju fun won

[6] Won wi pe: “Iwo ti Won so al-Ƙur’an kale fun, dajudaju were ni e

[7] Ki ni ko je ki iwo mu awon molaika wa ba wa, ti iwo ba wa ninu awon olododo?”

[8] A o nii so molaika kale bi ko se pelu ododo. Won ko si nii lo won lara mo nigba naa (ti awon molaika ba sokale)

[9] Dajudaju Awa l’A so Tira Iranti kale (iyen al-Ƙur’an). Dajudaju Awa si ni Oluso re

[10] Dajudaju siwaju re A ti ran (awon Ojise) nise si awon ijo, awon eni akoko

[11] Ojise kan ko si nii de ba won afi ki won fi se yeye

[12] Bayen ni A se n fi (aisan) sinu okan awon elese

[13] Won ko nii gba Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) gbo; ise (Allahu lori) awon eni akoko kuku ti re koja

[14] Ti o ba je pe A si ilekun kan sile fun won lati inu sanmo, ti won ko si ye gbabe gunke lo (sinu sanmo)

[15] dajudaju won a wi pe: “Won kuku lo isiju fun wa ni. Nse ni won n dan wa.”

[16] A kuku fi awon ibuso (irawo) sinu sanmo (aye). A si se e ni oso fun awon oluworan

[17] A si fi aabo bo imisi sanmo lodo gbogbo esu, eni eko

[18] Afi (esu) ti o ba ji oro gbo. Nigba naa si ni ogunna ponnbele yo tele e lati eyin

[19] Ile, A te e perese. A si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu re. A si mu gbogbo nnkan ti o ni odiwon hu jade lati inu re

[20] A se ona ije-imu sinu (ile aye) fun eyin ati awon ti eyin ko le pese fun

[21] Ko si si kini kan afi ki ile-oro re wa lodo Wa. Awa ko si nii so o kale afi pelu odiwon ti A ti mo

[22] Ati pe A ran ategun lati ko esujo jo. A si so omi kale lati sanmo. Nitori naa, A fun yin mu. Eyin si ko ni e ko omi ojo jo (soju sanmo)

[23] Dajudaju Awa, Awa ma l’A n so (eda) di alaaye. A si n so o di oku. Awa si ni A oo jogun (eda)

[24] Ati pe dajudaju A mo awon olugbawaju ninu yin. Dajudaju A si mo awon olugbeyin

[25] Dajudaju Oluwa re, Oun l’O maa ko won jo. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo

[26] Dajudaju A seda eniyan lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda

[27] Ati pe alujannu, A seda re siwaju (eniyan) lati ara ina alategun gbigbona ti ko ni eefin

[28] (Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: “Dajudaju Emi yoo se eda abara kan lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda

[29] Nigba ti Mo ba se e t’o gun rege tan, ti Mo fe emi si i (lara) ninu emi Mi (ti Mo da), nigba naa e doju bole fun un ni oluforikanle-kini

[30] Nitori naa, awon molaika, gbogbo won patapata si fori kanle ki i

[31] Ayafi ’Iblis. O ko lati wa ninu awon oluforikanle naa

[32] (Allahu) so pe: "’Iblis, ki l’o di o lowo lati wa ninu awon oluforikanle

[33] O wi pe: "Emi ko nii fori kanle ki abara kan ti O seda re lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda

[34] (Allahu) so pe: "Nitori naa, jade kuro ninu re. Dajudaju, iwo ni eni-eko

[35] Ati pe, dajudaju egun n be lori re titi di Ojo esan

[36] O wi pe: “Oluwa mi, lo mi lara titi di Ojo Ajinde.”

[37] (Allahu) so pe: "Dajudaju iwo wa lara awon ti A oo lo lara

[38] titi di ojo akoko ti A ti mo

[39] O wi pe: "Oluwa mi, fun wi pe O ti se mi ni eni anu, dajudaju emi yoo se (aburu) ni oso fun won lori ile. Dajudaju emi yo si ko gbogbo won sinu anu

[40] afi awon erusin Re, awon eni esa ninu won

[41] (Allahu) so pe: "(Idurosinsin loju) ona taara, Owo Mi ni eyi wa

[42] Dajudaju awon erusin Mi, ko si agbara kan fun o lori won, ayafi eni ti o ba tele o ninu awon eni anu

[43] Ati pe dajudaju ina Jahanamo ni adehun fun gbogbo won

[44] Awon oju ona meje n be fun (ina). Atunpin tun wa fun oju-ona kookan

[45] Dajudaju awon oluberu (Allahu) maa wa ninu awon Ogba Idera pelu awon odo (t’o n san nisale re)

[46] (A maa so pe): “E wo inu re pelu alaafia ni olufayabale.”

[47] A si maa yo ohun ti n be ninu okan won t’o je inunibini kuro; (won yoo di) omo-iya (ara won. Won yoo wa) lori ibusun, ti won yoo koju sira won

[48] Wahala kan ko nii ba won ninu re. Won ko si nii mu won jade kuro ninu re

[49] Fun awon erusin Mi ni iro pe dajudaju Emi ni Alaforijin, Asake-orun

[50] Ati pe dajudaju iya Mi ni iya eleta-elero

[51] Fun won ni iro nipa alejo (Anabi) ’Ibrohim

[52] (Ranti) nigba ti won wole to o, won si so pe: “Alaafia”. O so pe: “Dajudaju eru yin n ba awa.”

[53] Won so pe: "Ma se beru. Dajudaju awa yoo fun o ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin onimimo kan

[54] O so pe: "Se e n fun mi ni iro idunnu (nipa bibi omo) nigba ti ogbo ti de si mi? Iro idunnu wo ni e n fun mi na

[55] Won so pe: “A n fun o ni iro idunnu pelu ododo. Nitori naa, ma se wa lara awon olujakanmuna.”

[56] O so pe: “Ko ma si eni ti o maa jakanmuna ninu ike Oluwa Re bi ko se awon olusina.”

[57] O so pe: “Ki tun ni oro ti e ba wa, eyin Ojise?”

[58] Won so pe: "Dajudaju Won ran wa nise si ijo elese ni

[59] Afi ara ile (Anabi) Lut. Dajudaju awa yoo gba won la patapata

[60] Afi iyawo re; A ti ko kadara re (pe) dajudaju o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun

[61] Nigba ti awon Ojise de odo ara ile (Anabi) Lut

[62] (Anabi Lut) so pe: “Dajudaju eyin je ajoji eniyan.”

[63] Won so pe: “Rara, a wa sodo re nitori ohun ti won n seyemeji nipa re

[64] A mu ododo wa ba o ni. Ati pe dajudaju olododo ni awa

[65] Nitori naa, mu ara ile re jade ni apa kan oru. Ki o si tele won leyin. Eni kan ninu yin ko si gbodo siju wo eyin wo. Ki e si lo si aye ti won n pa lase fun yin

[66] A si je ki idajo oro yii han si i pe dajudaju A maa pa awon (elese) wonyi run patapata nigba ti won ba mojumo

[67] Awon ara ilu naa de, won si n yo sese

[68] (Anabi Lut) so pe: “Dajudaju awon wonyi ni alejo mi. Nitori naa, e ma se doju ti mi

[69] Ki e beru Allahu. Ki e si ma se yepere mi

[70] Won wi pe: “Nje awa ko ti ko fun o (nipa gbigba alejo) awon eda?”

[71] O so pe: “Awon omobinrin mi niwonyi, ti e ba ni nnkan ti e fe (fi won) se.”

[72] (Allahu so pe): “Mo fi isemi iwo (Anabi Muhammad) bura; dajudaju won kuku wa ninu idaamu opolo, ti won n pa ridarida.”

[73] Nitori naa, ohun igbe mu won nigba ti oorun owuro yo si won

[74] A si so oke ilu won di isale re (ilu won doju bole). A tun ro ojo okuta amo (sisun) le won lori

[75] Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon alariiwoye

[76] Dajudaju (ilu naa) kuku wa loju ona (ti e n to lo to bo)

[77] Dajudaju ami wa ninu iyen fun awon onigbagbo ododo

[78] Awon ara ’Aekah naa je alabosi

[79] A si gbesan lara won. Dajujaju awon ilu mejeeji l’o kuku wa loju ona gbangba (ti e n to lo to bo)

[80] Dajudaju awon ara Iho apata pe awon Ojise ni opuro

[81] A si fun won ni awon ami Wa. Amo won gbunri kuro nibe

[82] Won maa n gbe awon ile igbe ifayabale sinu awon apata

[83] Ohun igbe si mu won nigba ti won mojumo

[84] Ohun ti won n se nise ko si ro won loro (nibi iya)

[85] A ko seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin awon mejeeji bi ko se pelu ododo. Dajudaju Akoko naa maa de. Nitori naa, samojukuro ni amojukuro t’o rewa

[86] Dajudaju Oluwa re ni Eledaa, Onimo

[87] Dajudaju A fun o ni Sab‘u Mothani (iyen, surah al-Fatihah) ati al-Ƙur’an t’o tobi

[88] Iwo ko gbodo siju re wo ohun ti A fi se igbadun aye lorisirisi fun awon kan ninu won. Ma se banuje nitori won. Ki o si re apa re nile fun awon onigbagbo ododo

[89] Ki o si so pe: “Dajudaju emi ni olukilo ponnbele.”

[90] Gege bi A se so (iya) kale fun awon t’o n pin ododo mo iro

[91] awon ti won so al-Ƙur’an di ipinkupin-in

[92] Oluwa re fi Ara Re bura fun o pe, A maa bi gbogbo won ni ibeere

[93] nipa ohun ti won n se nise

[94] Nitori naa, kede nnkan ti A pa lase fun o. Ki o si seri kuro lodo awon osebo

[95] Dajudaju Awa yoo to o (nibi aburu) awon oniyeye

[96] awon t’o n mu olohun miiran mo Allahu. Laipe won maa mo

[97] Awa kuku ti mo pe dajudaju ohun ti won n wi n ko inira ba o

[98] Nitori naa, se afomo pelu idupe fun Oluwa re. Ki o si wa ninu awon oluforikanle (fun Un)

[99] Josin fun Oluwa re titi amodaju (iyen, iku) yoo fi de ba o

Oyìn

Surah 16

[1] Ase Allahu de tan. E ma wule wa a pelu ikanju. Mimo ni fun Un. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[2] (Allahu) n fi ase Re so molaika (Jibril) kale lati maa mu imisi wa diedie fun enikeni ti O ba fe (bee fun) ninu awon erusin Re nitori ki e le fi se ikilo pe: “Dajudaju ko si olohun kan ti ijosin to si afi Emi. Nitori naa, e beru Mi.”

[3] O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[4] O da eniyan lati inu ato. (Eniyan) si di olujiyan ponnbele (nipa Ajinde)

[5] Awon eran-osin, O seda won. Aso otutu ati awon anfaani (miiran) n be fun yin lara won. Ati pe e n je ninu won

[6] Oso tun n be fun yin lara won nigba ti e ba n da won lo (si ile won) ati nigba ti e ba n ko won jade lo jeko

[7] Won si n ru awon eru yin t’o wuwo lo si ilu kan ti e o le de afi pelu wahala emi. Dajudaju Oluwa yin ma ni Alaaanu, Onikee

[8] (O seda) esin, ibaaka ati ketekete nitori ki e le gun won. (Won tun je) oso. O tun n seda ohun ti e o mo

[9] Allahu l’O n salaye (’Islam) ona taara. Awon ona esin wiwo tun wa (loto) . Ti O ba fe bee ni, iba to gbogbo yin si ona (esin ’Islam)

[10] Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. Mimu wa fun yin ninu re. Igi eweko tun n wu jade lati inu re. E si n fi bo awon eran-osin

[11] (Allahu) tun n fi (omi yii) hu awon irugbin, igi ororo zaetun, igi dabinu, igi ajara ati gbogbo awon eso (yooku) jade fun yin. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle

[12] O ro oru, osan, oorun, osupa ati awon irawo fun yin pelu ase Re. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye

[13] Ati ohun ti O tun seda re fun yin lori ile, ti awon awo re je orisirisi. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o n lo iranti

[14] Oun ni Eni ti O ro agbami odo nitori ki e le je eran (eja) tutu ati nitori ki e le mu nnkan oso ti e oo maa wo sara jade lati inu (odo), - o si maa ri awon oko oju-omi ti yoo maa la oju omi koja lo bo – ati nitori ki e le wa ninu awon ajulo oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Allahu)

[15] O si fi awon apata t’o duro gbagidi sori ile ki o ma fi le mi mo yin lese ati awon odo ati awon oju-ona nitori ki e le da oju ona mo

[16] ati awon ami opopona (fun itosona irin osan). Won tun n fi irawo da oju ona mo (lale)

[17] Nje Eni ti O da eda da bi eni ti ko da eda bi? Nitori naa, se e o nii lo iranti ni

[18] Ti e ba sonka idera Allahu, e ko le ka a tan. Dajudaju Allahu ma ni Alaforijin, Onikee

[19] Ati pe Allahu mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n se afihan re

[20] Awon (orisa) ti won n pe leyin Allahu; won ko le da kini kan. Allahu l’O si seda won

[21] Oku (ni won), won ki i se alaaye. Won ko si mo akoko ti A oo gbe won dide. won ki i se alaaye.” ko so iku Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) di ohun t’o ti sele. Sebi awon molaika kan wa lara nnkan ti awon eniyan n josin fun leyin Allahu. Se oku ni awon molaika naa ni tabi alaaye? A o kuku ti i gbo iku molaika kan kan ri. Bakan naa as-Saton ar-Rojim je okan pataki ninu ohun ti awon eniyan n josin fun. Se oku ni Saeton naa ni tabi alaaye? Rara bi Allahu se fe.” Ko wa si eri taara kan kan t’o fi rinle pe Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ti ku bi ko se ayah oniponna eyi ti a ti se alaye lori re siwaju ninu itose-oro fun surah ali-’Imron 3:55. Dipo ki a ri ayah kan tabi hadith kan taara lori iku Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) hadith t’o n fi ipadabo re rinle l’a n ri. Eni ti ko i ku l’o si le pada wa sile aye. ” ninu ayah naa ki i se itumo adamo. Idi ni pe ere ti ko si emi lara re ni awon orisa naa. Ipo oku eni ti ko le soro

[22] Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Amo awon ti ko ni igbagbo ninu Ojo Ikeyin ni okan won tako o, ti won si n segberaga

[23] Ko si tabi-sugbon, dajudaju Allahu mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n se afihan re. Ati pe dajudaju (Allahu) ko nifee awon onigbeeraga

[24] Nigba ti won ba so fun won pe: “Ki ni Oluwa yin sokale? Won a wi pe: “Akosile alo awon eni akoko ni.”

[25] (Won so bee) nitori ki won le ru eru ese tiwon ni pipe perepere ni Ojo Ajinde ati (nitori ki won le ru) ninu eru ese awon ti won n si lona pelu ainimo. Gbo, ohun ti won yoo ru ni ese, o buru

[26] Awon t’o siwaju won kuku dete. Allahu si da ile won wo lati ipile. Orule si wo lu won mole lati oke won. Ati pe iya de ba won ni aye ti won ko ti fura

[27] Leyin naa, ni Ojo Ajinde (Allahu) yoo yepere won. O si maa so pe: “Ibo ni awon (ti e so di) akegbe Mi wa, awon ti e ti tori won yapa (Mi)?” Awon ti A fun ni imo esin yo si so pe: “Dajudaju abuku ati aburu ojo oni wa fun awon alaigbagbo.”

[28] (Awon ni) awon ti molaika n pa nigba ti won n sabosi si emi ara won lowo. Ni asiko yii ni won juwo juse sile (won si wi pe): “Awa ko se ise aburu kan kan.” Rara (e sise aburu)! Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti e n se nise

[29] Nitori naa, e wo awon enu ona Ina lo, olusegbere ni yin ninu re. Ibugbe awon onigbeeraga si buru

[30] Won so fun awon t’o beru (Allahu) pe: “Ki ni Oluwa yin sokale? Won a wi pe: “Rere ni.” Rere ti wa fun awon t’o se rere ni ile aye yii. Dajudaju Ile Ikeyin loore julo. Ati pe dajudaju ile awon oluberu (Allahu) dara

[31] Awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo inu re. Awon odo yo si maa san ni isale re. Ohunkohun ti won ba n fe maa wa fun won ninu re. Bayen ni Allahu se n san esan rere fun awon oluberu (Re)

[32] Awon ti molaika n pa, nigba ti won n se rere lowo, (awon molaika) n so pe: “Alaafia fun yin. E wo inu Ogba Idera nitori ohun ti e n se nise.”

[33] Se won n reti ohun kan yato si pe ki awon molaika wa ba won tabi ki ase Oluwa re de? Bayen ni awon t’o siwaju won ti se. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

[34] Nitori naa, awon aburu ohun ti won se nise sele si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po

[35] Awon ti won ba Allahu wa akegbe yo si wi pe: “Ti o ba je pe Allahu fe ni awa iba ti josin fun kini kan leyin Re, awa ati awon baba wa. Bakan naa, awa iba ti se kini kan ni eewo leyin Re.” Bayen ni awon t’o siwaju won ti se. Nje ojuse kan wa fun awon Ojise bi ko se ise-jije ponnbele

[36] Dajudaju A ti gbe Ojise dide ninu ijo kookan (lati jise) pe: “E josin fun Allahu. Ki e si jinna si awon orisa.” Nitori naa, o wa ninu won, eni ti Allahu to si ona. O si wa ninu won, eni ti isina ko le lori. Nitori naa, e rin kiri lori ile, ki e si woye si bi atubotan awon t’o pe awon Ojise ni opuro se ri

[37] Ti o ba n soju kokoro si imona won, eni ti Allahu ba si lona, dajudaju ko nii fi mona, ko si nii si awon alaranse kan kan fun won

[38] Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe: “Allahu ko nii gbe eni ti o ku dide.” Ko ri bee, (ajinde je) adehun lodo Allahu. Ododo si ni, sugbon opolopo eniyan ko mo

[39] (Allahu yoo gbe eda dide) nitori ki O le salaye ohun ti won n yapa enu si fun won ati nitori ki awon t’o sai gbagbo le mo pe dajudaju awon ni won je opuro

[40] Oro Wa fun kini kan nigba ti A ba gbero re ni pe, A maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee.”

[41] Awon t’o gbe ilu won ju sile nitori ti Allahu, leyin ti awon alaigbagbo ti sabosi si won, dajudaju Awa yoo wa ibugbe rere fun won. Esan Ojo Ikeyin si tobi julo, ti o ba je pe (awon ti ko se hijrah) mo

[42] (Awon ni) awon t’o se suuru, won si n gbarale Oluwa won

[43] A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si. Nitori naa, e beere lodo awon oniran-anti ti eyin ko ba mo. ki i se awon sufi. Idi ni pe okunfa ayah mejeeji yii ni pe

[44] (A fi) awon eri t’o yanju ati ipin-ipin Tira (ran won nise). Ati pe A so tira Iranti (iyen, al-Ƙur’an) kale fun o nitori ki o le salaye fun awon eniyan ohun ti A sokale fun won ati nitori ki won le ronu jinle

[45] Se awon t’o da ete aburu fi okan bale pe Allahu ko le mu ile ri mo won lese ni, tabi pe iya ko le de ba won lati aye ti won ko ti nii fura

[46] Tabi (Allahu) ko le gba won mu lori irinke-rindo won ni? Won ko si nii mori bo

[47] Tabi (Allahu) ko le maa gba won mu diedie ni? Nitori naa, dajudaju Oluwa yin ma ni Alaaanu, Onikee

[48] Ati pe se won ko ri gbogbo nnkan ti Allahu seda re, ti ooji re n pada yo lati otun ati osi ni oluforikanle fun Allahu; ti won si n yepere ara won (fun Un)

[49] Allahu si ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile ni nnkan abemi ati awon molaika n fori kanle fun. Won ko si segberaga

[50] Won n paya Oluwa won t’O n be loke won. Won si n se ohun ti A n pa lase fun won

[51] Allahu so pe: “E ma se josin fun olohun meji. Oun nikan ni Olohun Okan soso ti ijosin to si. Nitori naa, Emi (nikan) ni ki e beru.”

[52] TiRe si ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. TiRe si ni esin titi laelae Nitori naa, se (nnkan miiran) yato si Allahu ni eyin yoo maa beru ni

[53] Ohunkohun ti e ni ninu idera, lati odo Allahu ni. Leyin naa, ti owo inira ba te yin, Oun ni ki e maa pe (fun idande)

[54] Leyin naa, nigba ti O ba si mu inira naa kuro fun yin tan, nigba naa ni apa kan ninu yin yo si maa sebo si Oluwa won

[55] nitori ki won le sai moore si nnkan ti A fun won. Nitori naa, e maa gbadun nso. Laipe e maa mo

[56] Won n fi ipin kan ninu ohun ti A pese fun won lele fun ohun ti won ko mo. Mo fi Allahu bura, dajudaju won yoo bi yin leere nipa ohun ti e n da ni adapa iro

[57] Won tun n fi (bibi) awon omobinrin lele fun Allahu - Mimo ni fun Un (ko bimo). – Won si n fi ohun ti won n fe lele fun tiwon

[58] Nigba ti won ba fun okan ninu won ni iro idunnu (pe o bi) omobinrin, oju re yoo sokunkun, o si maa kun fun ibanuje

[59] O si maa fi ara pamo fun awon eniyan nitori iro aburu ti won fun un. Se o maa gba a ni nnkan abuku ni tabi o maa bo o mole laaye? E gbo, ohun ti won n da lejo buru

[60] Ti awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ni akawe aburu. Ti Allahu si ni akawe t’o ga julo. Ati pe Oun ni Alagbara, Ologbon

[61] Ti o ba je pe Allahu n gba awon eniyan mu nitori abosi owo won, iba ti se abemi kan kan ku sori ile. Sugbon O n lo won lara di gbedeke akoko kan. Nigba ti akoko naa ba de, won ko nii sun un siwaju di igba kan, won ko si nii fa a seyin.”

[62] Won n fi (omobinrin) nnkan ti won korira lele fun Allahu. Ahon won si n royin iro pe dajudaju rere ni tawon. Ko si tabi-sugbon, dajudaju Ina ni tiwon. Ati pe dajudaju won maa pa won ti sinu re ni

[63] Mo fi Allahu bura, dajudaju A ti ran awon Ojise nise si awon ijo kan siwaju re. Nigba naa, Esu se ise won ni oso fun won; oun si ni ore won lonii. Iya eleta-elero si wa fun won

[64] A ko so Tira naa kale fun o bi ko se pe ki o le salaye fun won ohun ti won n yapa enu si; o si je imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo

[65] Allahu l’O n so omi kale lati sanmo. O si n fi ji ile leyin ti o ti ku. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro (ododo)

[66] Dajudaju ariwoye wa fun yin lara awon eran-osin, ti A n fun yin mu ninu nnkan t’o wa ninu re, (eyi) ti o n jade wa lati aarin boto inu agbedu ati eje. (O si n di) wara mimo t’o n lo tinrin ni ofun awon t’o n mu un

[67] Ati pe lati ara awon eso dabinu ati eso ajara ni e ti n se oti ati ohun amu-soro t’o dara. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye

[68] Oluwa re si fi mo kokoro oyin pe: "Mu ile sinu apata, igi ati ohun ti (awon eniyan) mo ga

[69] Leyin naa, je lara gbogbo eso, ki o si to awon oju ona Oluwa re pelu iteriba." Ohun mimu ti awo re yato sira won yoo maa jade lati inu kokoro oyin. Iwosan ni fun awon eniyan. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle

[70] Allahu l’O seda yin. Leyin naa, O n gba emi yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da pada si ogbo kujokujo nitori ki o ma le mo nnkan kan mo leyin ti o ti mo on. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alagbara

[71] Allahu l’O soore ajulo fun apa kan yin lori apa kan ninu arisiki. Awon ti A fun ni oore ajulo, ki won fun awon eru won ni arisiki won, ki won si jo pin in ni dogbadogba! Nitori naa, se idera Allahu ni won yoo maa tako

[72] Ati pe Allahu se awon iyawo fun yin lati ara yin. O fun yin ni awon omo ati omoomo lati ara awon iyawo yin. O si pese arisiki fun yin ninu awon nnkan daadaa. Se iro (iyen, orisa) ni won yoo gbagbo, won yo si sai gbagbo ninu idera Allahu

[73] Dipo (ki won josin fun) Allahu, won n josin fun ohun ti ko ni ikapa arisiki kan kan fun won ninu sanmo ati ile; won ko si lagbara (lati se nnkan kan)

[74] Nitori naa, e ma se fi awon akawe naa lele nipa Allahu. Dajudaju Allahu nimo; eyin ko si nimo

[75] Allahu fi akawe kan lele (nipa) eru kan ti o wa labe oga, ti ko si le da nnkan kan se ati eni ti A fun ni arisiki t’o dara lati odo wa, ti o si n na ninu re ni ikoko ati ni gbangba. Se won dogba bi? Gbogbo ope n je ti Allahu. Sugbon opolopo won ni ko mo

[76] Allahu tun fi akawe kan lele (nipa) okunrin meji kan, ti okan ninu won je odi, ti ko le da nnkan kan se, ti o tun je wahala fun oga re (nitori pe) ibikibi ti o ba ran an lo, ko nii mu oore kan bo (fun un lati ibe). Se o dogba pelu eni ti O n pase sise eto, ti o si wa loju ona taara

[77] Ti Allahu ni ikoko awon sanmo ati ile. Oro Akoko naa ko kuku tayo iseju tabi ki o tun sunmo julo. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[78] Allahu l’O mu yin jade lati inu ikun awon iya yin nigba ti eyin ko ti i da nnkan kan mo. O si se igboro, awon iriran ati awon okan fun yin nitori ki e le dupe (fun Un)

[79] Se won ko woye si awon eye ti A ro (fun fifo) ninu ofurufu (labe) sanmo? Ko si eni t’o n mu won duro (sinu ofurufu) bi ko se Allahu. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo

[80] Allahu se ibusinmi fun yin sinu ile yin. Lati ara awo eran-osin, O tun se awon ile (atibaba) kan t’o fuye fun yin lati gbe rin ni ojo irin-ajo yin ati ni ojo ti e ba wa ninu ilu. Lati ara irun agutan, irun rakunmi ati irun ewure, e tun n ri awon nnkan oso ati nnkan igbadun lo titi fun igba die. aso eyi ti won ba fi irun agutan hun maa n je aso t’o roju julo ni rira. Nitori eyi aso irun agutan je aso awon mekunnu. Awon olowo ki i si fe ra a fun wiwo sorun nitori pe olufokansin eni esa onpero kookan ninu awon aafa onibidiah wonyen ba tun bere si fi oruko ara re pero dipo lilo oruko agbelero ti won dijo se adadaale re. Nigba naa ni aye won ba di ilana / toriko “at-tasowuffu al-kodiriyyah” ti okunrin kan ko ba ti ri ise halal se ni ise oojo o maa di “seeu”

[81] Allahu se awon iboji fun yin lati ara nnkan ti O da. O se awon ibugbe fun yin lati ara awon apata. O tun se awon aso fun yin t’o n daabo bo yin lowo ooru ati awon aso t’o n daabo bo yin loju ogun yin. Bayen l’O se n pe idera Re le yin lori nitori ki e le je musulumi

[82] Nitori naa, ti won ba gbunri, ise-jije ponnbele lojuse tire

[83] Won mo idera Allahu, leyin naa won n tako o. Opolopo won si ni alaimoore

[84] (Ranti) ojo ti A oo gbe elerii kan dide ninu gbogbo ijo (awon Anabi), leyin naa, A o nii yonda (aroye sise) fun awon t’o sai gbagbo. Won ko si nii fun won ni aye lati pada se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu

[85] Nigba ti awon t’o sabosi ba ri Iya, nigba naa, A o nii se iya won ni fifuye, A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina)

[86] Nigba ti awon t’o ba Allahu wa akegbe ba ri awon orisa won, won a wi pe: “Oluwa wa, awon wonyi ni awon orisa wa ti a n pe leyin Re.” Nigba naa (awon orisa) yoo ju oro naa pada si won pe: “Dajudaju opuro ma ni eyin.”

[87] Won si maa jura won sile fun Allahu ni ojo yen. Ohun ti won n da ni adapa iro yo si di ofo mo won lowo

[88] Awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, A o se alekun iya lori iya fun won nitori pe won n sebaje

[89] (Ranti) Ojo ti A oo gbe elerii dide fun ijo kookan laaarin ara won, A si maa mu iwo wa ni elerii fun awon wonyi. A so Tira kale fun o; (o je) alaye fun gbogbo nnkan, imona, ike ati iro idunnu fun awon musulumi

[90] Dajudaju Allahu n pase sise deede, sise rere ati fifun ebi (ni nnkan). O si n ko iwa ibaje, ohun buruku ati rukerudo. O n se waasi fun yin nitori ki e le lo iranti

[91] Ki e si mu adehun Allahu se nigba ti e ba se adehun. E ma se tu ibura leyin ifirinle re. E si kuku ti fi Allahu se Elerii lori ara yin. Dajudaju Allahu mo ohun ti e n se nise

[92] Ki e si ma se da bi (obinrin) eyi ti o tu owu didi re pale leyin ti o ti di i le. Nse ni e n lo ibura yin fun etan laaarin ara yin nitori pe iran kan po ju iran kan lo. Dajudaju Allahu n dan yin wo pelu re ni. Ati pe ni Ojo Ajinde O kuku maa salaye fun yin ohun ti e n yapa enu si

[93] Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon O n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Dajudaju Won maa bi yin leere nipa ohun ti e n se nise

[94] E ma se lo ibura yin fun etan laaarin ara yin, nitori ki ese yin ma baa ye gere leyin idurosinsin re, ati nitori ki e ma baa to iya buruku wo nipa bi e se seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Iya nla yo si wa fun yin

[95] E ma se ta adehun Allahu ni owo pooku. Ohun ti n be lodo Allahu, o loore julo fun yin ti e ba mo

[96] Ohun t’o n be lodo yin maa tan. Ohun t’o n be lodo Allahu si maa wa titi laelae. Dajudaju A si maa fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san awon t’o se suuru lesan won

[97] Enikeni ti o ba se ise rere, okunrin ni tabi obinrin, o si je onigbagbo ododo, dajudaju A oo je ki o lo igbesi aye t’o dara. Dajudaju A o si fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san won ni esan won

[98] Nigba ti o ba (fe) ke al-Ƙur’an, sa di Allahu nibi (aburu) Esu, eni eko

[99] Dajudaju ko si agbara kan fun un lori awon t’o gbagbo, ti won si n gbarale Oluwa won

[100] Eni t’o lagbara lori re ni awon t’o n mu un ni ore ati awon t’o so o di akegbe Allahu

[101] Nigba ti A ba paaro ayah kan si aye ayah kan, Allahu l’O si nimo julo nipa ohun t’O n sokale, won a wi pe: “Iwo kan je aladapa iro ni.” Amo opolopo won ni ko nimo

[102] So pe: “Emi mimo (molaika Jibril) l’o so o kale lati odo Oluwa re ni ti ododo nitori ki o le mu ese awon t’o gbagbo lododo rinle. (Ki o si le je) imona ati iro idunnu fun awon musulumi

[103] A si kuku ti mo pe dajudaju won n wi pe: “Sebi abara kan l’o n ko o (ni al-Ƙur’an).” Ede eni ti won n ye si (ti won n toka si pe o n ko o) ki i se elede Larubawa. Ede Larubawa ponnbele si ni (al-Ƙur’an) yii

[104] Dajudaju awon ti ko gbagbo ninu awon ayah Allahu, Allahu ko nii to won sona. Iya eleta-elero si wa fun won

[105] Awon ti ko gbagbo ninu awon ayah Allahu l’o n da adapa iro (mo Allahu). Awon wonyen si ni opuro

[106] Enikeni ti o ba sai gbagbo ninu Allahu leyin igbagbo re, yato si eni ti won je nipa, ti okan re si bale pelu igbagbo ododo, sugbon enikeni ti aigbagbo ba te lorun, ibinu lati odo Allahu n be lori won. Iya nla si wa fun won

[107] Iyen nitori pe won feran isemi aye ju orun. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo

[108] Awon wonyen ni awon ti Allahu ti fi edidi bo okan won, igboro won ati iriran won. Awon wonyen si ni afonufora

[109] Ko si tabi-sugbon, dajudaju awon ni olofo ni orun

[110] Leyin naa, dajudaju Oluwa re - nipa awon t’o gbe ilu won ju sile leyin ti awon alaigbagbo ti ko ifooro ba won, leyin naa, ti won jagun esin, ti won si se suuru - dajudaju Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun (fun won) leyin (ifooro ti won ri lodo awon alaigbagbo)

[111] (Ranti) Ojo ti emi kookan yoo de lati du ori ara re. A o si san emi kookan ni esan ohun ti o se nise; won ko si nii sabosi si won

[112] Allahu fi akawe lele nipa ilu kan, ti o je (ilu) aabo ati ifayabale, ti arisiki re n te e lowo ni pupo ni gbogbo aye. Amo (won) se aimoore si awon idera Allahu. Nitori naa, Allahu fun won ni iya ebi ati ipaya to wo nitori ohun ti won n se nise

[113] Ojise kuku ti de ba won laaarin ara won. Won si pe e ni opuro. Nitori naa, owo iya ba won. Alabosi si ni won

[114] E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin ni nnkan eto, t’o dara. Ki e si dupe oore Allahu ti o ba je pe Oun nikan soso ni e n josin fun

[115] Ohun ti (Allahu) se ni eewo fun yin ni eran okunbete, eje, eran elede ati eyi ti won pa pelu oruko t’o yato si “Allahu”. Nitori naa, enikeni ti won ba fi inira ebi kan, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[116] E ma se so nipa ohun ti ahon yin royin ni iro pe: “Eyi ni eto, eyi si ni eewo” nitori ki e le da adapa iro mo Allahu. Dajudaju awon t’o n da adapa iro mo Allahu, won ko nii jere

[117] Igbadun aye bin-intin (le wa fun won, amo) iya eleta-elero wa fun won (ni orun)

[118] Ati pe A se ohun ti A so fun o siwaju ni eewo fun awon t’o di yehudi. A o si sabosi si won, sugbon awon ni won n sabosi si emi ara won

[119] Leyin naa, dajudaju Oluwa re - nipa awon t’o se aburu pelu aimokan, leyin naa, ti won ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse leyin re dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, Asake-orun

[120] Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim je asiwaju-awokose-rere, olutele-ase Allahu, oluduro-deede-ninu-esin. Ko si je ara awon osebo

[121] O maa n dupe awon idera Allahu. Allahu sa a lesa. O si to o si ona taara (’Islam)

[122] A se ohun rere fun un nile aye. Ati pe ni orun dajudaju o maa wa ninu awon eni rere

[123] Leyin naa, A fi imisi ranse si o pe ki o tele esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-esin. Ko si wa lara awon osebo

[124] Awon ti won se (agbega) ojo Sabt fun ni awon t’o yapa enu nipa re. Dajudaju Oluwa re yoo kuku se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si

[125] Pepe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ijinle (iyen, al-Ƙur’an ati sunnah Anabi s.a.w.) ati waasi rere. Ki o si ja won niyan pelu eyi t’o dara julo. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni ti o sina kuro loju ona Re (’Islam). O si nimo julo nipa awon olumona (awon musulumi)

[126] Ti e (ba fe) gbesan (iya), e gbesan iru iya ti won fi je yin. Dajudaju ti e ba si se suuru, o ma si loore julo fun awon onisuuru

[127] Se suuru. Iwo ko si le ri suuru se afi pelu (iranlowo) Allahu. Ma se banuje nitori won. Ma si se wa ninu ibanuje nitori ohun ti won n da ni ete

[128] Dajudaju Allahu wa pelu awon t’o beru (Re) ati awon t’o n se rere

Ìrìn-àjò Òru

Surah 17

[1] Mimo ni fun Eni ti O mu erusin Re se irin-ajo ni ale lati Mosalasi Haram si Mosalasi Aƙso ti A fi ibukun yi ka, nitori ki A le fi ninu awon ami Wa han an. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran

[2] A fun (Anabi) Musa ni Tira. A si se e ni imona fun awon omo ’Isro’il. (A si so) pe: “E ma se mu alaabo kan leyin Mi.”

[3] (E je) aromodomo awon ti A gbe gun oko oju-omi pelu (Anabi) Nuh. Dajudaju (Nuh) je erusin, oludupe

[4] A si fi mo awon omo ’Isro’il ninu Tira pe: “Dajudaju e maa sebaje lori ile nigba meji. Dajudaju e tun maa segberaga t’o tobi.”

[5] Nitori naa, nigba ti adehun fun akoko ninu mejeeji ba sele, A maa gbe awon erusin Wa kan, ti won lagbara gan-an, dide si yin. Won yoo da rogbodiyan sile laaarin ilu (yin). O je adehun kan ti A maa mu se

[6] Leyin naa, A da isegun lori won pada fun yin. A si fi awon dukia ati awon omo se idera fun yin. A si se yin ni ijo t’o po julo

[7] Ti e ba se rere, e se rere fun emi ara yin. Ti e ba si se aburu, fun emi ara yin ni. Nigba ti adehun ikeyin ba de, (A oo gbe omo ogun miiran dide) nitori ki won le ko ibanuje ba yin ati nitori ki won le wo inu Mosalasi gege bi won se wo o nigba akoko ati nitori ki won le pa ohun ti (awon omo ’Isro’il) joba lori re run patapata

[8] O le je pe Oluwa yin maa saanu yin. Ti e ba si pada (sibi ese), A maa pada (sibi esan). A si se ina Jahanamo ni ewon fun awon alaigbagbo

[9] Dajudaju al-Ƙur’an yii, o n fini mona si ona taara, o si n fun awon onigbagbo ododo t’o n se awon ise rere ni iro idunnu pe dajudaju esan t’o tobi wa fun won

[10] Dajudaju awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo, A ti pese iya eleta-elero sile de won

[11] Eniyan n toro aburu bi o se n toro ohun rere; eniyan si je olukanju

[12] A se ale ati osan ni ami meji; A pa ami ale re, A si se ami osan ni iriran1 nitori ki e le wa oore ajulo lati odo Oluwa yin ati nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro. Gbogbo nnkan ni A ti salaye re ni ifosiwewe

[13] Eniyan kookan ni A ti la ayanmo ati iwe ise re bo lorun. A si maa mu iwe kan jade fun un ni Ojo Ajinde. O maa pade re ni sisi sile

[14] Ka iwe (ise) re. Iwo ti to ni olusiro fun emi ara re lonii

[15] Enikeni t’o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni t’o ba si sina, o n sina fun emi ara re. Eleru-ese kan ko nii ru ese elomiiran. A o si nii je awon eda niya titi A fi maa gbe ojise kan dide (si won)

[16] Nigba ti A ba si gbero lati pa ilu kan run, A maa pa awon onigbedemuke ilu naa lase (rere). Amo won maa sebaje sinu ilu. Oro naa yo si ko le won lori. A o si pa won re patapata

[17] Meloo meloo ninu awon iran ti A ti parun leyin (Anabi) Nuh! Oluwa re to ni Alamotan, Oluriran nipa awon ese erusin Re

[18] Eni ti o ba n gbero (oore) aye yii (nikan), A maa taari ohun ti A ba fe si i ninu re ni kiakia fun eni ti A ba fe. Leyin naa, A maa se ina Jahanamo fun un; o maa wo inu re ni eni yepere, eni eko

[19] Eni ti o ba si gbero (oore) orun, ti o si se ise re, o si je onigbagbo ododo, awon wonyen, ise won maa je atewogba (pelu esan rere)

[20] Awon wonyi (t’o n gbero oore aye) ati awon wonyi (t’o n gbero oore orun), gbogbo won ni A n se oore aye fun lati inu ore Oluwa re. Won ko nii di ore Oluwa re lowo (fun ikini keji nile aye)

[21] Wo bi A se fun apa kan won loore ajulo lori apa kan (nile aye). Dajudaju torun tun tobi julo ni ipo, o si tobi julo loore ajulo

[22] Ma se mu olohun miiran mo Allahu nitori ki o ma baa jokoo (sinu Ina) ni eni abuku, eni ti won maa da isoro re da

[23] Oluwa re pase pe: “E ma se josin fun eni kan ayafi Oun. Ki e si se daadaa si awon obi (yin) mejeeji. Ti okan ninu awon mejeeji tabi ikini keji won ba dagba si o lodo, ma se sio si won, ma se jagbe mo won. Maa ba awon mejeeji so oro aponle

[24] Ki o si re apa re nile lati fi bowo fun awon mejeeji nipa sise aanu won. Ki o si so pe: "Oluwa Eledaa mi, ke awon mejeeji gege bi won se re mi ni kekere

[25] Oluwa yin nimo julo nipa ohun ti n be ninu emi yin, ti e ba je eni rere. Dajudaju O n je Alaforijin fun awon oluronupiwada

[26] E fun ebi ni eto re. (E fun) mekunnu ati onirin-ajo ti agara da (ni nnkan). Ki e si ma se na dukia yin ni ina-apa

[27] Dajudaju awon apa, won je omo iya Esu. Alaimoore si ni Esu je si Oluwa re

[28] Ti o ba seri kuro lodo won (iyen awon alaini) lati wa ike kan ti o n reti lati odo Oluwa re, ba won soro ele

[29] Ma di owo re mo orun re (ma ya ahun), ma si te e sile tan patapata (ma ya apa), ki o ma baa jokoo kale ni eni eebu (ti o ba je ahun), eni ti ko nii si lowo re mo (ti o ba je apa)

[30] Dajudaju Oluwa re l’O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju O n je Onimo-ikoko, Oluriran nipa awon erusin Re

[31] E ma pa awon omo yin nitori ipaya osi. Awa l’A n pese fun awon ati eyin. Dajudaju pipa won je ese t’o tobi

[32] E ma se sunmo agbere. Dajudaju o je iwa buruku. O si buru ni oju ona

[33] E ma pa emi ti Allahu se (pipa re) ni eewo ayafi ni ona eto. Eni ti won ba pa ni ipa abosi, dajudaju A ti fun alamojuuto re ni agbara (lati gbesan). Nitori naa, ki enikeni ma se tayo enu- ala nibi ipaniyan (nitori pe) dajudaju A maa ran (ebi oku) lowo (lati gbesan)

[34] E ma se sunmo dukia omo orukan, ayafi ni ona t’o dara julo, titi o fi maa dagba. Ki e si mu adehun se. Dajudaju adehun je ohun ti A o beere nipa re

[35] E won osuwon kun nigba ti e ba won on. E fi iwon t’o to won on. Iyen loore julo, o si dara julo ni ikangun

[36] Ma se tele ohun ti iwo ko nimo nipa re. Dajudaju igboro, iriran ati okan; ikookan iwonyen ni A oo beere nipa re

[37] Ma se rin lori ile pelu igberaga; dajudaju iwo ko le da ile lu, iwo ko si le ga to apata

[38] Gbogbo iyen, aburu re je ohun ikorira lodo Oluwa re

[39] Iyen wa ninu ohun ti Oluwa re fi ranse si o ninu ijinle ogbon (al-Ƙur’an). Ma se mu olohun miiran mo Allahu ki won ma baa ju o sinu ina Jahanamo ni eni abuku, eni eko

[40] Se Oluwa yin fi awon omokunrin sa yin lesa, Oun wa mu awon omobinrin ninu awon molaika (ni tiRe)? Dajudaju e ma n so oro nla (t’o buru)

[41] Dajudaju A ti se alaye sinu al- Ƙur’an yii nitori ki won le lo isiti. Sibesibe ko se alekun kan fun won bi ko se sisa (fun iranti)

[42] So pe: “Ti o ba je pe awon olohun kan tun wa pelu Re gege bi won se n wi, won iba wa ona lati sunmo (Allahu) Onitee-ola ni.”

[43] Mimo ni fun Un. O si ga ni giga t’o tobi tayo ohun ti won n wi (ni aida nipa Re)

[44] Awon sanmo mejeeje, ile ati awon ti won wa ninu won n se afomo fun Un. Ko si si kini kan afi ki o se afomo ati idupe fun Un. Sugbon e ko le gbo agboye afomo won. Dajudaju Allahu n je Alafarada, Alaforijin

[45] Nigba ti o ba n ke al-Ƙur’an, A maa fi gaga aabo saaarin iwo ati awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo

[46] A fi ebibo bo okan won nitori ki won ma baa gbo o ye. (A tun fi) edidi sinu eti won. Nigba ti o ba si daruko Oluwa re nikan soso ninu al-Ƙur’an, won maa peyin won da lati sa lo

[47] Awa nimo julo nipa ohun ti won n gbo nigba ti won ba n teti si o ati nigba ti won ba n soro kelekele, nigba ti awon alabosi ba n wi pe: “E ko tele eni kan bi ko se okunrin eleedi kan.”

[48] Wo bi won se fun o ni awon afiwe (buruku)! Nitori naa, won ti sina; won ko si le mona

[49] Won wi pe: “Se nigba ti a ba ti di egungun, ti a ti jera, se Won maa gbe wa dide ni eda titun ni?”

[50] So pe: "E di okuta tabi irin

[51] Tabi (ki e di) eda kan ninu ohun ti o tobi ninu okan yin." Sibesibe won yoo wi pe: “Ta ni O maa da wa pada (fun ajinde)?” So pe: “Eni ti O pile iseda yin ni igba akoko ni.” Sibesibe won yoo mi ori won si o (ni ti abuku) Nigba naa, won yoo wi pe: “Igba wo ni?” So pe: “O le je pe o ti sunmo.”

[52] Ojo ti Allahu yoo pe yin. E si maa jepe pelu idupe fun Un. E si maa ro pe e ko gbe ile aye bi ko se fun igba die

[53] So fun awon erusin Mi pe ki won so oro eyi t’o dara julo. Dajudaju Esu yoo maa da yanpon-yanrin sile laaarin won. Dajudaju Esu je ota ponnbele fun eniyan

[54] Oluwa yin nimo julo nipa yin. Ti O ba fe, O maa ke yin. Tabi ti O ba si fe, O maa je yin niya. A ko ran o pe ki o je oluso lori won

[55] Oluwa re nimo julo nipa awon t’o n be ninu awon sanmo ati ile. Dajudaju A ti se oore ajulo fun apa kan awon Anabi lori apa kan. A si fun (Anabi) Dawud ni Zabur

[56] So pe: "E pe awon ti e so nipa won lai ni eri lowo pe won je olohun leyin Re, (e maa ri i pe) won ko ni ikapa lati gbe inira kuro tabi lati se iyipada kan fun yin

[57] Awon wonyen ti won n pe (leyin Re) n wa ategun sodo Oluwa won ni! - Ewo ninu won l’o sunmo (Allahu) julo (bayii)? – Awon naa n reti ike Allahu, won si n paya iya Re. Dajudaju iya Oluwa re je ohun ti won gbodo sora fun

[58] Ko si ilu kan (t’o sabosi) afi ki Awa pa a re siwaju Ojo Ajinde tabi ki A je e niya lile. Iyen wa ni kiko sile ninu Tira (Laohul-Mahfuth)

[59] Ati pe ko si ohun ti o di Wa lowo lati fi awon ami (ise iyanu) ranse bi ko se pe awon eni akoko ti pe e niro. A fun ijo Thamud ni abo rakunmi; (ami) t’o foju han kedere ni. Amo won sabosi si i. A o si nii fi awon ami ranse bi ko se fun ideruba

[60] (Ranti) nigba ti A so fun o pe: “Dajudaju Oluwa re yi awon eniyan po (pelu agbara Re). Ati pe A ko se iran (wiwo) ti A fi han o ati igi (zaƙum) ti A sebi le ninu al-Ƙur’an ni kini kan bi ko se pe (o je) adanwo fun awon eniyan. A n deru ba won, amo ko se alekun kan fun won bi ko se iwa agbere t’o tobi

[61] (Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: "E fori kanle ki (Anabi) Adam." Won si fori kanle ki i afi ’Iblis. O wi pe: “Se ki ng fori kanle ki eni ti O fi amo seda re ni?”

[62] O wi pe: "So fun mi nipa eyi ti O gbe aponle fun lori mi, (nitori ki ni?) Dajudaju ti O ba le lo mi lara di Ojo Ajinde, dajudaju mo maa jegaba lori awon aromodomo re afi awon die

[63] (Allahu) so pe: "Maa lo. Enikeni ti o ba tele o ninu won, dajudaju ina Jahanamo ni esan yin. (O si je) esan t’o kun keke

[64] Fi ohun re ko eni ti agbara re ba ka ninu won laya je. Fi awon omo ogun elesin re ati omo ogun elese re pe won (sinu isina). Kopa pelu won ninu awon dukia ati awon omo. Ki o si se ileri fun won." Esu ko si nii se ileri fun won bi ko se etan

[65] Dajudaju awon erusin Mi, ko si agbara kan fun o lori won. Oluwa re si to ni Oluso

[66] Oluwa yin ni Eni t’O n mu oko oju-omi rin fun yin nitori ki e le wa ninu oore ajulo Re. Dajudaju O n je Alaaanu fun yin

[67] Nigba ti inira ba fowo ba yin loju omi, eni ti e n pe yo si dofo (mo yin lowo) afi Oun nikan (Allahu). Nigba ti O ba si gba yin la (ti e) gunle, e n gbunri (kuro lodo Re). Eniyan si je alaimoore

[68] Se e fokan bale pe (Allahu) ko le mu apa kan ile ri mo yin lese ni? Tabi pe ko le fi okuta ina ranse si yin? Leyin naa, e o si nii ri oluso kan ti o maa gba yin la

[69] Tabi e fokan bale pe (Allahu) ko nii pada mu yin wa si (ori omi) nigba miiran ni; ti O maa ran iji ategun si yin, ti O si maa te yin ri (sinu omi) nitori pe e sai moore? Leyin naa, e o si nii ri oluranlowo kan t’o maa ba yin gbesan lara Wa

[70] Dajudaju A se aponle fun awon omo (Anabi) Adam; A gbe won rin lori ile ati lori omi; A fun won ni ije-imu ninu awon nnkan daadaa; A si soore ajulo fun won gan-an lori opolopo ninu awon ti A da

[71] Ni ojo ti A oo maa pe gbogbo eniyan pelu asiwaju won . Nigba naa, enikeni ti A ba fun ni iwe (ise) re ni owo otun re, awon wonyen ni won yoo maa ka iwe (ise) won. A o si nii sabosi bin-intin si won

[72] Enikeni ti o ba je afoju (nipa ’Islam) nile aye yii, oun ni afoju ni orun. O si (ti) sina julo

[73] Won fee ko iyonu ba o nipa nnkan ti A mu wa fun o ni imisi nitori ki o le hun nnkan miiran t’o yato si i nipa Wa. Nigba naa, won iba mu o ni ore ayo

[74] Ti ko ba je pe A fi ese re rinle ni, dajudaju o fee fi nnkan die te si odo won

[75] Nigba naa, Awa iba je ki o to ilopo (iya) isemi aye ati ilopo (iya leyin) iku wo. Leyin naa, iwo ko nii ri oluranlowo kan ti o maa gba o sile nibi iya Wa

[76] Won fee ko o laya je ninu ilu nitori ki won le le o jade kuro ninu re. Nigba naa, awon naa ko nii wa ninu re leyin re tayo igba die

[77] (Eyi je) ise (Allahu) lori awon ti A ti ran nise ninu awon Ojise Wa siwaju re. O o si nii ri iyipada kan fun ise Wa

[78] Gbe irun kiki duro ni (igba ti) oorun ba yetari titi di igba ti ale yoo fi le. Ati pe irun Subh, dajudaju irun Subh je ohun ti (awon molaika ale ati osan) yoo jerii si

[79] Ati pe ninu oru, fi kike al-Ƙur’an (lori irun) sai sun. (Eyi je) ise asegbore fun o. Laipe, Oluwa re yoo gbe o si aye ope

[80] So pe: “Oluwa mi, mu mi wo inu ilu ni iwolu ona ododo. Mu mi jade kuro ninu ilu ni ijade ona ododo. Ki O si fun mi ni aranse t’o lagbara lati odo Re

[81] So pe: “Ododo de. Iro si sa lo. Dajudaju iro je ohun ti o maa sa lo.”

[82] A n so ohun ti o je iwosan ati ike kale sinu al-Ƙur’an fun awon onigbagbo ododo. (al-Ƙur’an) ko si salekun fun awon alabosi bi ko se ofo

[83] Nigba ti A ba sedera fun eniyan, o maa gbunri (kuro nibi ododo), o si maa segberaga. Nigba ti aburu ba si fowo ba a, o maa di olusoretinu

[84] So pe: "Eni kookan n sise lori adamo re. Sugbon Oluwa yin nimo julo nipa eni ti o mona

[85] Won n bi o leere nipa emi. So pe: “Emi n be ninu ase Oluwa mi. A o si fun yin ninu imo bi ko se die.”

[86] Ati pe dajudaju ti A ba fe ni, A iba kuku gba imisi ti A fi ranse si o (kuro ni odo re). Leyin naa, iwo ko nii ri alaabo kan ti o maa la o lodo Wa

[87] Ayafi ike lati odo Oluwa re (ni ko fi se bee). Dajudaju oore ajulo Re lori re tobi

[88] So pe: “Dajudaju ti awon eniyan ati alujannu ba para po lati mu iru al-Ƙur’an yii wa, won ko le mu iru re wa, apa kan won ibaa je oluranlowo fun apa kan

[89] Dajudaju A ti fi akawe kookan salaye (orisirisi) fun awon eniyan sinu al-Ƙur’an yii. Sibesibe opolopo eniyan ko lati gba afi atako sa

[90] Won si wi pe: “A ko nii gba o gbo titi o maa fi mu omi iseleru se yo fun wa

[91] Tabi ki o ni ogba oko dabinu ati ogba oko ajara, ti o si maa je ki awon odo san ko ja daadaa laaarin won

[92] Tabi ki o je ki sanmo ja lu wa ni kelekele gege bi o se so (pe Allahu le se bee). Tabi ki o mu Allahu ati awon molaika wa (ba wa) ni ojukoju

[93] Tabi ki o ni ile wura kan, tabi ki o gun oke sanmo lo. A ko si nii gba gigun-sanmo re gbo titi o fi maa so tira kan ti a oo maa ke kale fun wa.” So pe: “Mimo ni fun Oluwa mi, nje mo je kini kan bi ko se Ojise abara?”

[94] Ko si ohun ti o ko fun awon eniyan lati gbagbo ni ododo nigba ti imona de ba won afi ki won wi pe: “Se Allahu ran Ojise abara nise ni?”

[95] So pe: “Ti o ba je pe awon molaika wa lori ile aye, ti won n rin kiri, (ti won n gbe lori ile) pelu ifayabale, A iba so molaika kan kale fun won lati inu sanmo (lati je) Ojise.”

[96] So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin. Dajudaju O n je Onimo-ikoko, Oluriran nipa awon erusin Re.”

[97] Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si lona, o o nii ri awon oluranlowo kan fun won leyin Re. Ati pe A maa ko won jo ni Ojo Ajinde ni idojubole. (Won yoo di) afoju, ayaya ati odi. Ina Jahanamo ni ibugbe won. Nigbakigba ti Ina ba jo loole, A maa salekun jijo (re) fun won

[98] Iyen ni esan won nitori pe, won sai gbagbo ninu awon ayah Wa. Won si wi pe: “Se nigba ti a ba ti di egungun, ti a si ti jera, se won tun maa gbe wa dide ni eda titun ni?”

[99] Se won ko ri i pe dajudaju Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile lagbara lati seda iru won (miiran)? O si maa fun won ni gbedeke akoko kan, ti ko si iyemeji ninu re. Sibesibe awon alabosi ko lati gba afi atako sa

[100] So pe: “Ti o ba je pe eyin l’e ni ikapa lori awon ile oro ike Oluwa mi ni, nigba naa eyin iba diwo mo on ni ti iberu osi. Eniyan si je ahun

[101] Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni awon ami mesan-an t’o yanju. Bi awon omo ’Isro’il leere wo. Ranti, nigba ti o de odo won, Fir‘aon wi fun un pe: “Dajudaju emi lero pe eleedi ni o, Musa.”

[102] (Anabi Musa) so pe: “O kuku mo pe ko si eni ti o so awon (ami) wonyi kale bi ko se Oluwa awon sanmo ati ile; (o si je) ami t’o yanju. Dajudaju emi naa lero pe eni iparun ni o, Fir‘aon.”

[103] Nitori naa, (Fir‘aon) fe ko won laya je lori ile. A si te oun ati awon t’o wa pelu re ri patapata

[104] A si so fun awon omo ’Isro’il leyin (iku) re pe: “E maa gbe ori ile naa. Sugbon nigba ti Adehun Ikeyin ba de, A oo mu gbogbo yin wa ni apapo (ni ojo esan)

[105] A so al-Ƙur’an kale pelu ododo. O si sokale pelu ododo. A ko si ran o nise bi ko se pe (ki o je) oniroo-idunnu ati olukilo

[106] Ati pe al-Ƙur’an, A salaye re (fun o) nitori ki o le ke e fun awon eniyan pelu pelepele. A si so o kale diedie. orisi isokale meji l’o wa fun al-Ƙur’an. Isokale kiini ni isokale olodidi lati inu Laohul-Mahfuth sinu sanmo ile aye. Isokale yii l’o sele ninu oru Laelatul-ƙodr. Eyi l’o jeyo ninu surah al-Baƙorah; 2:185 surah ad-Dukan; 44:3 ati surah al-Ƙodr’ 97:1. Isokale keji ni isokale onidiedie lati inu sanmo ile aye sori ile aye. Eyi sele fun onka odun metalelogun. Isokale yii ni ayah yii n so nipa re

[107] So pe: “E gba al-Ƙur’an gbo tabi e o gba a gbo, dajudaju awon ti A fun ni imo siwaju (isokale) re, nigba ti won ba n ke e fun won, won yoo doju bole, ti won n fori kanle (fun Allahu)

[108] Won n so pe: “Mimo ni fun Oluwa wa. Dajudaju adehun Oluwa wa maa wa si imuse ni.”

[109] Won n doju bole, ti won n sunkun (fun Allahu. Al-Ƙur’an) si n salekun iteriba fun won

[110] So pe: “E pe Allahu tabi e pe ar-Rahmon (Ajoke-aye).” Eyikeyii ti e ba fi pe E (ninu re), sebi tiRe ni awon oruko t’o dara julo. Ma se kigbe lori irun (ati adua) re. Ma si se wa ni idake roro. Wa ona saaarin mejeeji yen

[111] Ki o si so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti ko fi eni kan se omo. Ko si ni akegbe ninu ijoba. Ko yepere ambosibosi pe O maa wa bukata si oluranlowo.” Gbe titobi fun Un gan-an

Àpátapò

Surah 18

[1] Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O so Tira kale fun erusin Re. Ko si doju oro kan ru ninu re

[2] (al-Ƙur’an) fese rinle nitori ki (Anabi) le fi se ikilo iya lile lati odo (Allahu) ati nitori ki (Anabi) le fun awon onigbagbo ododo, awon t’o n se ise rere ni iro idunnu pe dajudaju esan rere n be fun won (ninu Ogba Idera)

[3] Won yoo maa gbe ninu re lo titi laelae

[4] Ati nitori ki (Anabi) le se ikilo fun awon t’o wi pe: “Allahu mu eni kan ni omo.”

[5] Ko si imo fun awon ati baba won nipa re. Oro t’o n jade lenu won tobi. Dajudaju won ko wi kini kan bi ko se iro

[6] Nitori naa, nitori ki ni o se maa fi ibanuje para re lori igbese won pe won ko gba oro (al-Ƙur’an) yii gbo

[7] Dajudaju Awa se ohun ti n be lori ile ni oso fun ara-aye nitori ki A le dan won wo (pe) ewo ninu won l’o maa dara julo nibi ise sise (fun esin)

[8] Ati pe dajudaju Awa maa so nnkan ti n be lori (ile) di erupe gbigbe ti ko nii hu irugbin

[9] Tabi o lero pe dajudaju awon ara inu iho apata ati walaha oruko won je eemo kan ninu awon ami Wa

[10] Nigba ti awon odokunrin naa kora won sinu iho apata, won so pe: “Oluwa wa, fun wa ni ike lati odo Re, ki O se imona ni irorun fun wa ninu oro wa.”

[11] A kun won l’oorun asunpiye ninu iho apata f’odun gbooro

[12] Leyin naa, A gbe won dide nitori ki A le safi han ewo ninu ijo mejeeji l’o mo gbedeke onka odun t’o lo (ninu iho apata naa)

[13] Awa n so iroyin won fun o pelu ododo. Dajudaju odokunrin ni won. Won gbagbo ninu Oluwa won. A si salekun imona fun won

[14] A si ki won lokan nigba ti won dide, ti won so pe: "Oluwa wa ni Oluwa awon sanmo ati ile. A o si nii pe olohun kan leyin Re. (Ti a ba pe olohun kan leyin Re) dajudaju a ti pa iro niyen

[15] Awon ijo wa wonyi so awon kan di olohun leyin Allahu. Ki ni ko je ki won mu eri t’o yanju wa nipa won? Nitori naa, ta ni o se abosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu

[16] (Awon odokunrin naa so funra won pe:) nigba ti e ba yera fun awon ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu, ti e si wa ibugbe sinu iho apata, Oluwa yin yoo te ninu ike Re sile fun yin. O si maa se oro yin ni irorun fun yin

[17] O maa ri oorun nigba ti o ba yo, o maa yeba kuro nibi iho won si owo otun. Nigba ti o ba tun wo, o maa fi won sile si owo osi. Won si wa ninu aye ti o feju ninu iho apata. Iyen wa ninu awon ami Allahu. Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si lona, o o si nii ri oluranlowo atoni-sona kan fun un

[18] O maa lero pe won laju sile ni, oju oorun ni won si wa. A si n yi won legbee pada sotun-un sosi. Aja won si na apa re mejeeji sile ni gbagede apata. Ti o ba je pe o yoju wo won ni, iwo iba peyin da lati ho fun won, iwo iba si kun fun iberu-bojo lati ara won

[19] Bayen (ni won wa) ti A fi gbe won dide pada nitori ki won le bi ara won leere ibeere. Onsoro kan ninu won so pe: “Igba wo le ti wa nibi?” Won so pe: “A wa nibi fun ojo kan tabi idaji ojo.” Won so pe: “Oluwa yin nimo julo nipa igba ti e ti wa nibi.” Nitori naa, e gbe okan ninu yin dide lo si inu ilu pelu owo fadaka yin yii. Ki o wo ewo ninu ounje ilu l’o mo julo, ki o si mu ase wa fun yin ninu re. Ki o se pelepele, ko si gbodo je ki eni kan kan fura si yin

[20] (Nitori pe) dajudaju ti won ba fi le mo nipa yin, won yoo ju yin loko tabi ki won da yin pada sinu esin won. (Ti o ba si fi ri bee) e o nii jere mo laelae niyen

[21] Bayen ni A se je ki awon eniyan ri won nitori ki won le mo pe dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ati pe dajudaju Akoko naa ko si iyemeji ninu re. Ranti (nigba ti awon eniyan) n se ariyanjiyan laaarin ara won nipa oro won. Won so pe: "E mo ile kan le won lori. Oluwa won nimo julo nipa won." Awon t’o bori lori oro won si wi pe: “Dajudaju a maa so ori apata won di mosalasi.”

[22] Won n wi pe: “Meta ni won. Aja won sikerin won.” Won tun n wi pe: "Marun-un ni won. Aja won sikefa won." Oro t’o pamo fun won (ni won n so). Won tun n wi pe: “Meje ni won. Aja won sikejo won.” So pe: "Oluwa mi nimo julo nipa onka won. Ko si (eni ti) o mo (onka) won afi awon die. Nitori naa, ma se ba won se ariyanjiyan nipa (onka) won afi (ki o fi) ariyanjiyan (naa ti sibi eri) t’o yanju (ti A sokale fun o yii). Ma si se bi eni kan ninu won leere nipa (onka) won

[23] Ma se so nipa kini kan pe: “Dajudaju emi yoo se iyen ni ola.”

[24] Ayafi (ki o fi kun un pe) "ti Allahu ba fe." Se iranti Oluwa re nigba ti o ba gbagbe (lati so bee lasiko naa). Ki o si so (fun won) pe: “O rorun ki Oluwa mi to mi sona pelu eyi ti o sunmo ju eyi lo ni imona (fun yin).”

[25] Won wa ninu iho apata won fun ogorun-un meta odun. Won tun lo alekun odun mesan-an

[26] So pe: “Allahu nimo julo nipa ohun ti won lo (ninu iho apata). TiRe ni ikoko awon sanmo ati ile. Ki ni ko ri tan, ki si ni ko gbo tan! Ko si alaabo kan fun won leyin Re. Ko si fi eni kan se akegbe ninu idajo Re.”

[27] Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira Oluwa re. Ko si eni ti o le yi awon oro Re pada. Iwo ko si le ri ibusasi kan yato si odo Re

[28] Se suuru fun emi re lati wa pelu awon t’o n pe Oluwa won ni owuro ati ni asale, ti won n wa Oju rere Re. Ma se foju pa won re lati wa oso isemi aye (yii). Ma si se tele eni ti A mu okan re gbagbe iranti Wa. O tele ife-inu re; oro re si je aseju

[29] So pe: “Ododo (niyi) lati odo Oluwa yin. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o gbagbo. Eni ti o ba si fe ki o sai gbagbo. Dajudaju Awa pese Ina sile de awon alabosi, ti ogba re yoo yi won po. Ti won ba n toro omi mimu, A oo fun won ni omi mimu kan t’o da bi oje ide gbigbona, ti (igbona re) yo si maa se awon oju. O buru ni mimu. O si buru ni ibukojo

[30] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, dajudaju Awa ko nii fi esan eni ti o ba se ise rere rare

[31] Awon wonyen, tiwon ni Ogba Idera gbere, ti awon odo yoo maa san ni isale won. Won yoo maa fi goolu orun se won ni oso ninu re. Won yoo maa wo aso aran alawo eweko (eyi ti o) fele ati (eyi ti) o nipon. Won yo si rogboku lori ibusun ola ninu (Ogba Idera). O dara ni esan. O si dara ni ibukojo

[32] Fi awon okunrin meji kan se apeere fun won; A fun okan ninu won ni ogba eso ajara meji. A si fi awon igi dabinu yi won ka. A tun fi awon igi eleso la won laaarin

[33] Ikini keji awon oko mejeeji n so eso won. Awon eso re ki i pe din. A si je ki odo san koja laaarin oko mejeeji

[34] O ni eso (se). O si so fun ore re nigba ti o n ba a jiyan (bayii) pe: “Emi ni dukia lowo ju o lo. Mo tun lero leyin julo.”

[35] O wo inu oko re lo, o si ti sabosi si emi ara re, o wi pe: “Emi ko lero pe eyi maa parun laelae

[36] Emi ko si lero pe Akoko naa maa sele. Ati pe ti won ba da mi pada si odo Oluwa mi, dajudaju mo tun maa ri ibudesi t’o dara ju eyi lo.”

[37] Ore re so fun un nigba ti o n ja a niyan (bayii) pe: “Se o maa sai gbagbo ninu Eni ti O seda re lati inu erupe, leyin naa, lati inu ato. Leyin naa, O se o ni okunrin t’o pe ni eda

[38] Sugbon ni temi, Oluwa mi, Oun ni Allahu. Emi ko si nii so eni kan di akegbe fun Oluwa mi

[39] Nigba ti o wo inu ogba oko re, ki ni ko mu o so pe: "Ohun ti Allahu ba fe! Ko si agbara kan bi ko se pelu iyonda Allahu. Ti o ba si ri mi pe mo kere si o ni dukia ati omo

[40] o sunmo ki Oluwa mi fun emi naa ni ogba oko ti o maa dara ju ogba oko tire. (O si sunmo) ki O so iya kan kale sinu ogba oko re lati sanmo; o si maa di ile asale

[41] Tabi ki omi re gbe. O o si nii le wa omi kan

[42] Won si pa eso re run patapata. O si di eni t’o n fi owo re mejeeji lura won peepe nipa ohun ti o ti na sori re. O ti parun torule-torule re. O si n wi pe: “Yee! Emi iba ti so eni kan kan di akegbe fun Oluwa mi.”

[43] Ko ni ijo kan ti o maa ran an lowo mo leyin Allahu. Ko si le ran ara re lowo

[44] Nibe yen, ti Allahu, Oba Ododo ni ijoba. O loore julo ni esan, O si loore julo ni ikangun (rere)

[45] Se akawe ile aye fun won; o da bi omi ti A sokale lati sanmo. Leyin naa, o ropo mo irugbin ile. Leyin naa, (irugbin) di gbigbe, ti ategun n fonka. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan

[46] Oso isemi aye ni dukia ati awon omo. Awon ise rere t’o maa wa titi laelae loore julo ni esan lodo Oluwa re, o si loore julo ni ireti

[47] (Ranti) ojo ti A maa mu awon apata rin lo. O si maa ri ile ni petele. A maa ko won jo. A o si nii fi eni kan sile ninu won

[48] Won yo si ko won wa siwaju Oluwa re ni owoowo. Dajudaju e ti wa ba Wa (bayii) gege bi A se da yin nigba akoko. Amo e so lai ni eri lowo pe A o nii mu ojo adehun se fun yin

[49] A maa gbe iwe ise eda kale (fun won). Nigba naa, o maa ri awon elese ti won yoo maa beru nipa ohun ti n be ninu iwe ise won. Won yoo wi pe: “Egbe wa! Iru iwe wo ni eyi na; ko fi ohun kekere ati nla kan sile lai ko o sile?” Won si ba ohun ti won se nise nibe. Oluwa re ko si nii sabosi si eni kan

[50] (Ranti) nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki (Anabi) Adam.” Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, (ti) o je okan ninu awon alujannu. O si safojudi si ase Oluwa re. Nitori naa, se e maa mu oun ati awon aromodomo re ni alafeyinti leyin Mi ni, ota yin si ni won. Pasipaaro t’o buru ni fun awon alabosi

[51] Ng o pe won si dida awon sanmo ati ile, ati dida awon gan-an alara. Ng o si mu awon asinilona ni oluranlowo

[52] (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo so pe: “E pe awon akegbe Mi ti e so nipa won lai ni eri lowo (pe olusipe ni won).” Won pe won. Won ko si da won lohun. A si ti fi koto iparun saaarin won

[53] Awon elese si ri Ina. Won si mo pe awon yoo ko sinu re. Won ko si nii ri ibusasi kan ninu re

[54] Dajudaju A ti se alaye oniran-anran sinu al-Ƙur’an fun awon eniyan pelu gbogbo akawe. Eniyan si je alatako pupo ju ohunkohun lo

[55] Ko si ohun t’o di awon eniyan lowo lati gbagbo nigba ti imona de ba won, (ko si si ohun t’o di won lowo lati) toro aforijin Oluwa won, bi ko se pe (won fe) ki ise (Allahu nipa iparun) awon eni akoko de ba awon naa tabi ki iya de ba won ni ojukoju

[56] Ati pe A ko ran awon Ojise nise (lasan) afi ki won je oniroo-idunnu ati olukilo. Awon t’o sai gbagbo si n fi iro satako nitori ki won le fi wo ododo. Won si so awon ayah Mi ati ohun ti A fi sekilo fun won di yeye

[57] Ta si l’o sabosi ju eni ti won fi awon ayah Oluwa re seranti fun, ti o gbunri kuro nibe, ti o si gbagbe ohun ti owo re mejeeji ti siwaju? Dajudaju Awa fi ebibo bo okan won nitori ki won ma baa gbo o ye. A si fi edidi sinu eti won. Ti iwo ba pe won sinu imona, nigba naa won ko si nii mona laelae

[58] Oluwa re, Alaforijin, Onikee, ti o ba je pe O maa fi ohun ti won se nise mu won ni, iba tete mu iya wa fun won. Sugbon akoko adehun (ajinde) wa fun won. Won ko si nii ri ibusasi kan leyin re

[59] Iwonyi ni awon ilu ti A ti pare nigba ti won sabosi. A si fun won ni adehun fun iparun won

[60] (Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun omo-odo re pe: "Ng o nii ye rin titi mo maa fi de ibi ti odo meji ti pade tabi (titi) mo maa fi lo opolopo odun

[61] Nigba ti awon mejeeji si de ibi ti odo meji ti pade, won gbagbe eja won. (Eja naa) si bo si oju ona re (ti o ti di) poro ona ninu odo

[62] Nigba ti awon mejeeji re koja (ibi ti odo meji ti pade), o so fun omo-odo re pe: "Fun wa ni ounje osan wa. Dajudaju a ti ko wahala ninu irin-ajo wa yii

[63] (Omo-odo re) so pe: "So (ohun t’o sele) fun mi, nigba ti a wa nibi apata! Dajudaju mo ti gbagbe eja naa (sibe)? Ko si si ohun ti o mu mi gbagbe re bi ko se Esu, ti ko je ki ng ranti re. (Eja naa) si ti mu ona re to lo ninu odo pelu iyanu

[64] (Anabi Musa) so pe: “(Ibi ti eja ti lo) yen ni ohun ti a n wa.” Awon mejeeji si pada seyin lati to oripa ese won bi won se to o wa

[65] Awon mejeeji si ri erusin kan ninu awon erusin Wa, ti A fun ni ike kan lati odo Wa. A si fun un ni imo lati odo Wa

[66] (Anabi) Musa so fun un pe: “Se ki ng tele o nitori ki o le ko mi ninu ohun ti Won fi mo o ni imona.” amo bi musulumi kookan ba se sunmo Allahu to ninu igbagbo ati iberu re nipa lilo ofin esin ’Islam

[67] (Kidr) so pe: “Dajudaju o o le se suuru pelu mi

[68] Ati pe bawo ni o se le se suuru lori ohun ti o o fi imo rokiri ka re?”

[69] (Anabi Musa) so pe: “Ti Allahu ba fe, o maa ba mi ni onisuuru. Mi o si nii yapa ase re.”

[70] (Kidr) so pe: “Ti o ba tele mi, ma se bi mi ni ibeere nipa nnkan kan titi mo fi maa koko mu iranti wa fun o nipa re.”

[71] Nitori naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi wo inu oko oju-omi. (Kidr) si da oko naa lu. (Anabi Musa) so pe: “O se da a lu, (se) ki awon ero re le te ri ni? Dajudaju o ti se nnkan aburu kan!”

[72] (Kidr) so pe: “Nje mi o so fun o pe dajudaju o o nii le se suuru pelu mi.”

[73] (Anabi Musa) so pe: “Ma se ba mi wi nipa ohun ti mo gbagbe. Ma si se ko inira ba mi ninu oro (irin-ajo) mi (pelu re).”

[74] Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won fi pade omodekunrin kan. (Kidr) si pa a. (Anabi Musa) so pe: “O se pa emi (eniyan) mimo, lai gba emi? Dajudaju o ti se nnkan t’o buru o.”

[75] (Kidr) so pe: “Nje mi o so fun o pe dajudaju o o nii le se suuru pelu mi.”

[76] (Anabi Musa) so pe: “Ti mo ba tun bi o nipa kini kan leyin re, ma se ba mi rin mo. Dajudaju o ti mu awawi de opin lodo mi.”

[77] Leyin naa, awon mejeeji lo titi di igba ti won de odo awon ara ilu kan. Won toro ounje lodo awon ara ilu naa. Won si ko lati se won ni alejo. Awon mejeeji si ba ogiri kan nibe ti o fe wo. (Kidr) si gbe e dide. (Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe o ba fe, o o ba si gba owo-oya lori re.”

[78] (Kidr) so pe: “Eyi ni opinya laaarin emi ati iwo. Mo si maa fun o ni itumo ohun ti o o le se suuru lori re.”

[79] Ni ti oko oju-omi, o je ti awon mekunnu ti won n sise lori omi. Mo si fe lati fi alebu kan an (nitori pe) oba kan wa niwaju won t’o n gba gbogbo oko oju-omi pelu ipa

[80] Ni ti omodekunrin naa, awon obi re mejeeji je onigbagbo ododo. A si n beru pe ki o maa ko itayo enu-ala ati aigbagbo ba awon mejeeji

[81] Nitori naa, A fe ki Oluwa awon mejeeji paaro re fun won pelu (eyi) t’o loore ju u lo ni ti mimo (ninu ese) ati (eyi) t’o sunmo ju u lo ni ti ike

[82] Nipa ti ogiri, o je ti awon omodekunrin, omo orukan meji kan ninu ilu naa. Apoti-oro kan si n be fun awon mejeeji labe ogiri naa. Baba awon mejeeji si je eni rere. Nitori naa, Oluwa re fe ki awon mejeeji dagba (ba dukia naa), ki won si hu dukia won jade (ki o le je) ike kan lati odo Oluwa re. Mi o da a se lati odo ara mi; (Allahu l’O pa mi lase re). Iyen ni itumo ohun ti o o le se suuru fun

[83] Won n bi o leere nipa Thul-Ƙorneen. So pe: “Mo maa mu oro iranti wa fun yin nipa re.”

[84] Dajudaju Awa fun un ni ipo lori ile. A si fun un ni ona t’o le gba se gbogbo nnkan (ti o ba fe se)

[85] Nitori naa, o mu ona kan to

[86] titi o fi de ibuwo oorun aye. O ri i ti n wo sinu iseleru petepete dudu kan. O si ba awon eniyan kan nibe. A so fun un pe: “Thul-Ƙorneen, yala ki o je won niya tabi ki o mu ohun rere jade lara won.”

[87] (Allahu) so pe: “Ni ti eni ti o ba sabosi, laipe A maa je e niya. Leyin naa, won maa da a pada si odo Oluwa re. O si maa je e niya t’o buru

[88] Sugbon ni ti eni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, tire ni esan rere. A o si soro irorun fun un ninu ase Wa.”

[89] Leyin naa, o mu ona kan to

[90] titi o fi de ibuyo oorun aye. O ri i ti n yo lori awon eniyan kan, ti A ko fun ni gaga (aabo) kan nibi oorun

[91] Bayen ni (Thul-Ƙorneen se n te siwaju). Dajudaju A rokirika ohun ti n be lodo re pelu imo

[92] Leyin naa, o mu ona kan to

[93] titi o fi de aarin apata meji. O si ba awon eniyan kan niwaju re. Won ko si fee gbo agboye oro kan (ninu ede miiran)

[94] Won so pe: “Thul-Ƙorneen, dajudaju (iran) Ya’juj ati Ma’juj n se ibaje lori ile. Se ki a fun o ni owo-ode nitori ki o le ba wa mo odi kan saaarin awa ati awon?”

[95] O so pe: "Ohun ti Oluwa mi fun mi ninu ipo loore julo. Nitori naa, e fi agbara ran mi lowo ni nitori ki ng le mo odi saaarin eyin ati awon

[96] E maa fun mi ni egige irin titi di igba ti o fi maa ba egbe apata mejeeji dogba." O so pe: "E maa fe ategun ewiri (si i lara) titi di igba ti o maa (pon wee bi) ina." O so pe: "E mu ide wa fun mi ki ng yo o le e lori

[97] Nitori naa, won ko le gun un, won ko si le da a lu

[98] O so pe: “Eyi ni ike kan lati odo Oluwa mi. Nigba ti adehun Oluwa mi ba de, (Allahu) yo si so o di petele. Adehun Oluwa mi si je ododo.”

[99] A maa fi awon (eniyan ati alujannu) sile ni ojo yen, ti apa kan won yo si maa dapo mo apa kan. Won a fon fere oniwo fun ajinde. A o si ko gbogbo won jo papo patapata

[100] Ni ojo yen, A o si fi ina Jahanamo han awon alaigbagbo kedere

[101] (Awon ni) awon ti oju won wa ninu ebibo nipa iranti Mi. Won ko si le gboro

[102] Se awon t’o sai gbagbo lero pe awon yoo mu awon erusin Mi ni oluranlowo leyin Mi ni? Dajudaju Awa pese ina Jahanamo sile ni ibudesi fun awon alaigbagbo

[103] So pe: “Se ki A fun yin ni iro awon eni ofo julo nipa ise (owo won)

[104] (Awon ni) awon ti ise won ti baje ninu isemi aye, (amo ti) won n lero pe dajudaju awon n se ise rere

[105] Awon wonyen ni awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Oluwa won ati ipade Re. Awon ise won si baje. Nitori naa, A o nii je ki won jamo nnkan kan lori iwon ni Ojo Ajinde

[106] Jahanamo, iyen ni esan won nitori pe won sai gbagbo, won si so awon ayah Mi ati awon Ojise Mi di oniyeye

[107] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, awon ogba Firdaos ti wa fun won ni ibudesi

[108] Olusegbere ni won ninu re. Won ko si nii fe kuro ninu re

[109] So pe: “Ti o ba je pe ibudo je tadaa fun awon oro Oluwa Mi, ibudo kuku maa tan siwaju ki awon oro Oluwa Mi to tan, koda ki A tun mu (ibudo) iru re wa ni alekun.”

[110] So pe: “Abara ni emi bi iru yin. Won n fi imisi ranse si mi pe Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, enikeni ti o ba n reti ipade Oluwa re, ki o se ise rere. Ko si gbodo fi eni kan kan se akegbe nibi jijosin fun Oluwa re.”

Mọryamù

Surah 19

[1] Kaf ha ya ‘aen sod. iya ‘Isa ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) Oun l’O sa a lesa. Tohun ti bee naa iba ti so awon ododo wonyen nipa Moryam iya Jesu. Sebi won kuku fi enu abuku kan Moryam eda ni awon miiran ti Allahu fi sori awon surah oro Re. A kuku ri surah Muhammad gege bi a se ri surah Moryam. Amo iya ‘Isa so surah l’o maa so ‘Isa tabi iya re di oluwa ati olugbala? Tabi se nitori pe won fi oruko Moryam iya ‘Isa so surah l’o so ‘Isa tabi iya re di olohun omo? Tabi se nitori pe won fi oruko Moryam sise ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) se Moryam ni esa eniyan amo ti Allahu ko se iya ati baba Anabi wa bee ti Allahu fi sori ebi Moryam a kuku ri surah Ƙuraes

[2] (Eyi ni) iranti nipa ike ti Oluwa Re se fun erusin Re, (Anabi) Zakariyya

[3] (Ranti) nigba ti o pe Oluwa re ni ipe ikoko

[4] O so pe: "Oluwa mi, dajudaju eegun ara mi ti le, ori (mi) ti kun fun ewu, emi ko si nii pasan nipa bi mo se n pe O, Oluwa mi

[5] Ati pe dajudaju mo n paya awon ibatan mi leyin (iku) mi. Iyawo mi si je agan. Nitori naa, ta mi lore lati odo Re omo rere kan

[6] (ti) o maa jogun mi, ti o si maa jogun awon ebi (Anabi) Ya‘ƙub. Ki O si se e ni eni ti O yonu si, Oluwa mi

[7] Zakariyya, dajudaju Awa maa fun o ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin kan, oruko re ni Yahya. A o fun eni kan ni (iru) oruko (yii) ri siwaju (re)

[8] O so pe: "Oluwa mi, bawo ni mo se maa ni omo nigba ti iyawo mi je agan, ti mo si ti di agbalagba gan-an

[9] (Molaika) so pe: “Bayen ni (o maa ri).” Oluwa re so pe: “O rorun fun Mi. Mo kuku da iwo naa siwaju (re), nigba ti iwo ko ti i je nnkan kan.”

[10] (Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, fun mi ni ami kan.” (Molaika) so pe: "Ami re ni pe, o o nii le ba eniyan soro fun ojo meta, ki i se ti amodi

[11] Nigba naa, o jade si awon eniyan re lati inu ile ijosin. O si toka si won pe ki won maa se afomo (fun Allahu) ni owuro ati ni asale

[12] Yahya, mu Tira naa dani daradara. A si fun un ni agboye esin lati kekere

[13] (Anabi Yahya je) ike ati eni mimo kan lati odo Wa. O si je oluberu (Allahu)

[14] (O tun je) oniwa rere si awon obi re mejeeji. Ko si je ajeninipa, oluyapa

[15] Alaafia ni fun un ni ojo ti won bi i, ati ni ojo ti o maa ku ati ni ojo ti A oo gbe e dide laaye (ni Ojo Ajinde)

[16] So itan Moryam ti o wa ninu al-Ƙur’an. (Ranti) nigba ti o yera kuro lodo awon eniyan re si aye kan ni ila oorun

[17] O mu gaga kan (lati fi ara re pamo) fun won. A si ran molaika Wa si i. O si fara han an ni aworan abara pipe

[18] (Moryam) so pe: “Emi sa di Ajoke-aye kuro lodo re, ti o ba je oluberu (Allahu).”

[19] (Molaika) so pe: “Emi ni Ojise Oluwa re, (O ran mi si o) pe ki ng fun o ni omokunrin mimo kan.”

[20] O so pe: "Bawo ni mo se maa ni omo nigba ti abara kan ko fowo kan mi, ti emi ko si je alagbere

[21] (Molaika) so pe: “Bayen l’o maa ri.” Oluwa re so pe: “O rorun fun mi. Ati pe nitori ki A le se e ni ami fun awon eniyan ni. O si je ike lati odo Wa. O tun je oro ti A ti pari.”

[22] Nitori naa, o loyun re. O si yera pelu re si aye kan t’o jinna

[23] Irobi omo si mu un wa si idi igi dabinu. O so pe: “Haa! Ki ng ti ku siwaju eyi, ki ng si ti di eni ti won ti gbagbe patapata.”

[24] Nigba naa, (molaika) pe e lati isale odo re pe: "Ma se banuje. Dajudaju Oluwa re ti se odo kekere kan si isale odo re

[25] Mi igi dabinu naa sodo re, ki dabinu tutu, to to ka je si maa jabo sile fun o

[26] Nitori naa, je, mu ki oju re si tutu. Ti o ba si ri eni kan ninu abara, so fun un pe: "Dajudaju mo jejee ikenuro fun Ajoke-aye. Nitori naa, mi o nii ba eniyan kan soro ni oni

[27] O si mu omo naa wa ba awon eniyan re (ni eni ti) o gbe e dani. Won so pe: "Moryam, dajudaju o ti gbe nnkan aburu nla wa

[28] Arabinrin Harun, baba re ki i se eniyan buruku. Ati pe iya re ki i se alagbere

[29] O si toka si omo naa. Won so pe: “Bawo ni a o se ba eni t’o wa lori ite, t’o je omo oponlo soro?”

[30] (Omo naa) soro pe: "Dajudaju eru Allahu ni emi. (Allahu) fun mi ni Tira. O si se mi ni Anabi. eda ti o n bowo fun ilana ati ofin Olohun eda ti o juwo juse sile fun ilana ati ofin Olohun ati eda ti o n josin fun Olohun labe ilana ati ofin Olohun. Eda naa ko si nii yonu si ilana ati ofin miiran t’o yato si ti Olohun.” Eni ti o ba n se iwonyen fun ohun miiran tabi elomiiran but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Itumo: “Nitori naa nigba naa pelu emi mi pelu okan ati ara wa ni a fi gba lati wa labe ofin Re. Iwonba asise ti a ba si fi ara se gege bi adamo eniyan ironupiwada ati itoro aforijin ni odo Allahu ni ona abayo lori re. Alaforijin

[31] O se mi ni eni ibukun ni ibikibi ti mo ba wa. O pa mi lase irun kiki ati Zakah yiyo lodiwon igba ti mo ba wa nipo alaaye (lori ile aye)

[32] (O se mi ni) oniwa rere si iya mi. Ko si se mi ni ajeninipa, olori buruku

[33] Alaafia ni fun mi ni ojo ti won bi mi, ati ni ojo ti mo maa ku ati ni ojo ti Won a gbe mi dide ni alaaye (ni Ojo Ajinde)

[34] Iyen ni (Anabi) ‘Isa omo Moryam. (Eyi je) oro ododo ti awon (yehudi ati nasara) n seyemeji nipa re

[35] Ko ye fun Allahu lati so eni kan kan di omo. Mimo ni fun Un. Nigba ti O ba pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee

[36] Ati pe dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara

[37] Awon ijo (yehudi ati nasara) si yapa enu (si eyi) laaarin ara won. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo (ni asiko) ijerii gbangba lojo nla (Ojo Ajinde)

[38] Ki ni won ko nii gbo, ki si ni won ko nii ri ni ojo ti won yoo wa ba Wa! Sugbon awon alabosi ni ojo naa ti wa ninu isina ponnbele

[39] Sekilo ojo abamo fun won nigba ti A ba pari oro, (pe ko nii si iku mo, amo) won wa ninu igbagbera bayii na, won ko si gbagbo

[40] Dajudaju Awa l’A maa jogun ile ati awon t’o n be lori re. Odo Wa si ni won yoo da yin pada si

[41] Mu (itan) ’Ibrohim wa si iranti (bi o se) wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olododo ponnbele, (o si je) Anabi

[42] Ranti nigba ti o so fun baba re pe: "Baba mi, nitori ki ni o fi n josin fun ohun ti ko gboro, ti ko riran, ti ko si le ro o loro kan kan

[43] Baba mi, dajudaju imo ti iwo ko ni ti de ba mi. Nitori naa, tele mi, ki ng fi ona taara mo o

[44] Baba mi, ma se bo Esu. Dajudaju Esu je oluyapa ase Ajoke-aye

[45] Baba mi, dajudaju emi n paya pe ki iya kan lati odo Ajoke-aye ma fowo ba o nitori ki iwo ma baa di ore Esu (ninu Ina)

[46] (Baba re) wi pe: “Se iwo yoo ko awon olohun mi sile ni, ’Ibrohim? Dajudaju ti o o ba jawo (ninu ohun ti o n so), dajudaju mo maa le o loko pa. Tie yera fun mi woorowo na.”

[47] (’Ibrohim) so pe: "Alaafia ki o maa ba o. Mo maa ba o toro aforijin lodo Oluwa mi. Dajudaju O je Oloore mi

[48] Ati pe mo maa yera fun eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu. Emi yo si maa pe Oluwa mi. O si sunmo pe emi ko nii pasan pelu adua mi si Oluwa mi

[49] Nigba ti o yera fun awon ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu, A si ta a lore (omo), ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (omoomo). A si se okookan won ni Anabi

[50] Ati pe A ta won lore lati inu ike Wa. A si ni ki won maa soro won ni daadaa

[51] So itan (Anabi) Musa ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je eni-esa, o je Ojise, (o tun je) Anabi

[52] A pe e ni eba apata ni apa owo otun (Musa). A si mu un sunmo tosi lati ba a soro

[53] Lati inu ike Wa A si fi arakunrin re, Harun, (ti o je) Anabi, ta a lore

[54] So itan (Anabi) ’Ismo‘il ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olumu-adehun-se, o je Ojise, (o tun je) Anabi

[55] O maa n pa ara ile re ni ase irun kiki ati Zakah yiyo. O si je eni iyonu lodo Oluwa re

[56] So itan (Anabi) ’Idris ti o wa ninu al-Ƙur’an. Dajudaju o je olododo ponnbele, (o si je) Anabi

[57] A si gbe e si aye giga (ninu sanmo)

[58] Awon wonyen ni awon ti Allahu se idera fun ninu awon Anabi, ninu awon aromodomo (Anabi) Adam ati ninu awon ti A gbe gun oko oju-omi pelu (Anabi) Nuh ati ninu aromodomo (Anabi) ’Ibrohim ati ’Isro’il ati ninu awon ti A ti fi mona, ti A si sa lesa. Nigba ti won ba n ke awon ayah Ajoke-aye fun won, won maa doju bole; ti won a forikanle, ti won a si maa sunkun

[59] Awon arole kan si role leyin won, ti won ra irun kiki lare, ti won tele awon yodoyindin emi. Laipe won maa pade iparun (ninu Ina)

[60] Ayafi eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni won yoo wo inu Ogba Idera. A o si nii sabosi kan kan si won

[61] (Won yoo wo inu) awon Ogba Idera gbere ti Ajoke-aye se ni adehun si ipamo fun awon erusin Re. Dajudaju (Allahu), adehun Re n bo wa se

[62] Won ko nii gbo isokuso ninu re afi alaafia. Ije-imu won wa ninu re ni owuro ati ni asale

[63] Iyen ni Ogba Idera ti A oo jogun re fun eni ti o je oluberu (Mi) ninu awon erusin Wa

[64] Awa (molaika) ki i sokale ayafi pelu ase Oluwa re. TiRe ni ohun ti n be niwaju wa, ohun ti n be ni eyin wa ati ohun ti n be laaarin (mejeeji) yii. Oluwa re ki i si se onigbagbe

[65] Oluwa awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin awon mejeeji. Nitori naa, josin fun Un, ki o si se suuru lori ijosin Re. Nje o mo eni ti o tun n je oruko Re

[66] Eniyan n wi pe: “Se nigba ti mo ba ku, Won yoo tun mu mi jade laipe ni alaaye?”

[67] Se eniyan ko ranti pe dajudaju Awa ni A seda re teletele nigba ti ko ti i je nnkan kan

[68] Nitori naa, mo fi Oluwa re bura; dajudaju A maa ko awon ati awon esu jo. Leyin naa, dajudaju A maa mu won wa si ayika ina Jahanamo lori ikunle

[69] Leyin naa, dajudaju A maa mu jade ninu ijo kookan eyikeyii ninu won ti o le julo ni ese dida si Ajoke-aye

[70] Leyin naa, dajudaju Awa nimo julo nipa awon t’o letoo si wiwo inu Ina

[71] Ko si eni kan ninu yin afi ki o debe. O je isele dandan lodo Oluwa re. 74:30-31. Bakan naa, kalmoh “warid” t’o jeyo ninu ayah 71 je oro-oruko ti won seda lati ara oro-ise “warada”. Ninu al-Ƙur’an, itumo meji pere l’o wa fun “warada”. “Warada” tumo si “o de si ibi ti kini kan wa, o si wo inu nnkan naa”, gege bi itumo yii se wa ninu surah Hud 11:98 ati surah al-’Anbiya’

[72] igun kiini keji maa wa labe akorin awon molaika kan ni. Iyen ni pe awon molaika kan l’o maa ko gbogbo eda lo sori afara Ina nitori pe

[73] Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awon t’o sai gbagbo yoo so fun awon t’o gbagbo ni ododo pe: “Ewo ninu ijo mejeeji (awa tabi eyin) l’o loore julo ni ibugbe, l’o si dara julo ni ijokoo?”

[74] Ati pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won, ti won dara julo ni oro (aye) ati ni irisi

[75] So pe: “Eni ti o ba wa ninu isina, Ajoke-aye yo si fe (isina) loju fun un taara, titi di igba ti won maa ri ohun ti won n se ni adehun fun won, yala iya tabi Akoko naa. Nigba naa, won yoo mo eni ti o buru julo ni ipo, ti o si le julo ni omo ogun

[76] Allahu yo si salekun imona fun awon t’o mona. Awon ise rere elesan gbere loore julo ni esan, o si loore julo ni ibudesi lodo Oluwa re

[77] So fun mi nipa eni t’o sai gbagbo ninu awon ayah Wa, ti o si wi pe: “Dajudaju won yoo fun mi ni dukia ati omo!”

[78] Se o ri ikoko ni tabi o ri adehun kan gba lodo Ajoke-aye

[79] Rara. A maa sakosile ohun t’o n wi. A si maa fe iya loju fun un taara

[80] A o si jogun ohun t’o n wi fun un. O si maa wa ba Wa ni oun nikan

[81] Won so awon kan di olohun leyin Allahu nitori ki won le fun won ni agbara

[82] Rara. Won maa tako ijosin won, won si maa di ota won

[83] Se o o ri i pe dajudaju Awa n ran awon esu si awon alaigbagbo ni, ti won si n ti won ni itikuti (sibi ese)

[84] Nitori naa, ma se kanju nipa (iya) won. A kuku n ka (ojo) fun won ni kika taara

[85] (Ranti) ojo ti A oo ko awon oluberu (Allahu) jo sodo Ajoke-aye lori nnkan igun

[86] A si maa da awon elese lo sinu ina Jahanamo witiwiti

[87] Won ko nii ni ikapa isipe afi eni ti o ba gba adehun lati odo Ajoke-aye

[88] Won wi pe: "Ajoke-aye fi eni kan se omo

[89] Dajudaju e ti mu nnkan aburu wa

[90] Awon sanmo fere faya perepere nitori re, ile fere faya perepere, awon apata si fere da wo lule gbi

[91] fun wi pe won pe eni kan ni omo Ajoke-aye

[92] Ko si ye fun Ajoke-aye lati fi eni kan se omo

[93] Ko si eni kan ninu awon sanmo ati ile ayafi ki o wa ba Ajoke-aye ni ipo erusin

[94] Dajudaju (Allahu) mo won. O si ka onka won taara

[95] Gbogbo won yo si wa ba A ni Ojo Ajinde ni ikookan

[96] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, Ajoke-aye yoo fi ife saaarin won

[97] Nitori naa, A kuku se kike al-Ƙur’an ni irorun (fun o) pelu ede abinibi re nitori ki o le fi se iro idunnu fun awon oluberu (Allahu) ati nitori ki o le fi se ikilo fun ijo oniyan-jija

[98] Meloo meloo ninu iran ti A ti pare siwaju won! Nje o gbo iro eni kan kan ninu won mo tabi (nje) o gbo ohun kelekele kan lati odo won bi

Ṭā-hā

Surah 20

[1] To ha

[2] A ko so al-Ƙur’an kale fun o lati ko wahala ba o

[3] Bi ko se pe o je iranti fun eni t’o n paya (Allahu)

[4] (O je) imisi t’o sokale lati odo Eni ti O da ile ati awon sanmo giga

[5] Ajoke-aye gunwa sori Ite-ola

[6] TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu

[7] Ti o ba so oro jade, dajudaju (Allahu) mo ikoko ati ohun ti o (tun) pamo julo

[8] Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. TiRe ni awon oruko t’o dara julo

[9] Nje oro (Anabi) Musa de odo re

[10] (Ranti) nigba ti o ri ina kan, o so fun awon ara ile re pe: “E duro sibi. Dajudaju emi ri ina kan. O see se ki ng ri ogunna mu wa fun yin ninu re tabi ki ng ri oju ona kan nitosi ina naa.”

[11] Nigba ti o de ibe, A pe e "Musa

[12] Dajudaju Emi ni Oluwa re. Nitori naa, bo bata re mejeeji sile. Dajudaju iwo wa ni afonifoji mimo, Tuwa

[13] Ati pe Emi sa o lesa. Nitori naa, fi eti si ohun ti A maa fi ranse si o ninu imisi

[14] Dajudaju Emi ni Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Emi. Nitori naa, josin fun Mi. Ki o si kirun fun iranti Mi

[15] Dajudaju Akoko naa n bo. O sunmo ki Ng safi han re (pelu awon ami. Akoko naa wa fun) ki A le san emi kookan ni esan nnkan ti o se nise

[16] Nitori naa, eni ti ko gba a gbo, ti o si tele ife-inu re, ma se je ki o seri re kuro nibe, ki o ma baa parun

[17] Ki ni iyen lowo otun re, Musa

[18] O so pe: “Opa mi ni. Mo n fi rogboku. Mo tun n fi ja ewe fun awon agutan mi. Mo si tun n lo o fun awon bukata miiran.”

[19] (Allahu) so pe: “Ju u sile, Musa.”

[20] Nigba naa, o ju u sile. O si di ejo t’o n sare

[21] (Allahu) so pe: "Mu un dani, ma si se beru. A maa da a pada si irisi re akoko

[22] Fi owo re mo (abe) apa re, o maa jade ni funfun, ti ki i se taburu. (O tun je) ami miiran

[23] Ki A le fi eyi t’o tobi ninu awon ami Wa han o

[24] Lo si odo Fir‘aon. Dajudaju o ti tayo enu-ala

[25] (Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, si okan mi paya fun mi

[26] Soro mi dirorun fun mi

[27] Tu koko ori ahon mi

[28] ki won maa gbo oro mi ye

[29] Ati pe fun mi ni amugbalegbee kan ninu awon ara ile mi

[30] Harun, arakunrin mi ni

[31] Fi kun mi lowo

[32] Fi sakegbe mi ninu ise mi

[33] ki a le safomo (oruko) Re ni opolopo

[34] ki a tun le seranti Re ni opolopo

[35] Dajudaju Iwo n ri wa.”

[36] (Allahu) so pe: "Dajudaju A ti fun o ni ibeere re, Musa

[37] Ati pe dajudaju A ti se oore fun o nigba kan ri

[38] (Ranti) nigba ti A sipaya ohun ti A sipaya fun iya re

[39] pe: “Ju Musa sinu apoti. Ki o si gbe e ju sinu agbami odo. Odo yo si gbe e ju si eti odo. Ota Mi ati ota re si maa gbe e.” Mo si da ife lati odo Mi bo o nitori ki won le toju re loju Mi.”

[40] (Ranti) nigba ti arabinrin re n rin lo, o si so pe: “Se ki ng juwe eni ti o maa gba a to (fun yin)?” A si da o pada sodo iya re nitori ki o le ni itutu oju, ko si nii banuje. Ati pe o pa emi eni kan. A si mu o kuro ninu ibanuje. A tun mu awon adanwo kan ba o. O tun lo awon odun kan lodo awon ara Modyan. Leyin naa, o de (ni akoko) ti o ti wa ninu kadara, Musa

[41] Mo si sa o lesa fun (ise) Mi

[42] Lo, iwo ati arakunrin re, pelu awon ami (ise iyanu) Mi. Ki e si ma se kole ninu iranti Mi

[43] E lo ba Fir‘aon. Dajudaju o ti tayo enu-ala

[44] E so oro ele fun un. O see se ki o lo isiti tabi ki o paya (Mi)

[45] Awon mejeeji so pe: “Oluwa wa, dajudaju awa n paya pe o ma yara je wa niya tabi pe o ma tayo enu-ala.”

[46] (Allahu) so pe: “E ma se paya. Dajudaju Emi wa pelu eyin mejeeji; Mo n gbo (yin), Mo si n ri (yin).”

[47] Nitori naa, e lo ba a, ki e so fun un pe: “Dajudaju Ojise Oluwa re ni awa mejeeji. Nitori naa, je ki awon omo ’Isro’il maa ba wa lo. Ma se fiya je won. Dajudaju a ti mu ami kan wa ba o lati odo Oluwa re. Ki alaafia si maa ba eni ti o ba tele imona

[48] Dajudaju Won ti fi imisi ranse si wa pe dajudaju iya n be fun eni ti o ba pe ododo niro, ti o si keyin si i

[49] (Fir‘aon) wi pe: “Ta ni Oluwa eyin mejeeji, Musa?”

[50] (Anabi Musa) so pe: “Oluwa wa ni Eni ti O fun gbogbo nnkan ni iseda re. Leyin naa, O to o si ona.”

[51] (Fir‘aon) wi pe: “Ki l’o mu awon iran akoko (ti won ko fi mona)?”

[52] (Anabi Musa) so pe: "Imo re wa ninu tira kan lodo Oluwa mi. Oluwa mi ko nii sasise. Ko si nii gbagbe

[53] (Oun ni) Eni ti O te ile ni perese fun yin. O si la awon ona sinu re fun yin. O si so omi kale lati sanmo. A si fi mu orisirisi jade ninu awon irugbin ni otooto

[54] E je, ki e si fi bo awon eran-osin yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon onilaakaye

[55] Lati ara erupe ni A ti da yin. Inu re si ni A oo da yin pada si. Lati inu re si ni A oo ti mu yin jade pada nigba miiran

[56] Dajudaju A ti fi awon ami Wa han an, gbogbo re. Amo o pe e niro. O si ko jale

[57] O wi pe: "Se o wa ba wa nitori ki o le mu wa jade kuro lori ile wa pelu idan re ni, Musa

[58] Dajudaju a maa mu idan iru re wa ba o. Nitori naa, mu akoko ipade laaarin awa ati iwo, ti awa ati iwo ko si nii yapa re, (ki o si mu) aye kan t’o teju

[59] (Anabi Musa) so pe: “Akoko ipade yin ni ojo Oso (iyen, ojo odun). Ki won si ko awon eniyan jo ni iyaleta.”

[60] Fir‘aon peyin da. O si sa ete re jo mora won. Leyin naa, o de (sibe)

[61] (Anabi Musa) so pe: “Egbe yin o! E ma se da adapa iro mo Allahu nitori ki O ma baa fi iya pa yin re. Ati pe dajudaju enikeni ti o ba da adapa iro (mo Allahu) ti sofo.”

[62] Won foro jomi toro oro laaarin ara won. Won si te soro

[63] Won wi pe: "Dajudaju awon mejeeji yii, opidan ni won o. Won fe mu yin jade kuro lori ile yin pelu idan won ni. Won si (fe) gba oju ona yin t’o dara julo mo yin lowo

[64] Nitori naa, e ko ete yin jo papo mora won. Leyin naa, ki e to wa ni owoowo. Dajudaju eni ti o ba bori ni oni ti jere

[65] (Awon opidan) wi pe: “Musa, iwo ni o maa koko ju (opa sile ni) tabi awa ni a oo koko ju u sile.”

[66] (Musa) so pe: “E ju (tiyin) sile (na).” Nigba naa ni awon okun won ati opa won ba n yira pada loju re nipase idan won, bi eni pe dajudaju won n sare

[67] (Anabi) Musa si pa eru inu okan re mora

[68] A so pe: "Ma se paya. Dajudaju iwo, iwo lo maa leke

[69] Ju ohun ti n be ni owo otun re sile. O si maa gbe ohun ti won se kale mi kalo. Dajudaju ohun ti won se kale, ete opidan ni. Opidan ko si nii jere ni ibikibi ti o ba de

[70] Nitori naa, ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan doju bole ni oluforikanle (fun Allahu). Won wi pe: "A gbagbo ninu Oluwa Harun ati Musa

[71] (Fir‘aon) wi pe: "Se e ti gba a gbo siwaju ki ng to yonda fun yin? Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Nitori naa, dajudaju mo maa ge awon owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Dajudaju mo tun maa kan yin mo awon igi dabinu. Dajudaju eyin yoo mo ewo ninu wa ni iya (re) yoo le julo, ti o si maa pe julo

[72] (Awon opidan) so pe: "Awa ko nii gbola fun o lori ohun ti o de ba wa ninu awon eri t’o daju, (a o si nii gbola fun o lori) Eni ti O seda wa. Nitori naa, da ohun ti o ba fe da lejo. Ile aye yii nikan ni o ti le dajo

[73] Dajudaju awa gba Oluwa wa gbo nitori ki O le se aforijin awon ese wa fun wa ati ohun ti o je wa nipa se ninu idan pipa. Allahu loore julo, O si maa wa titi laelae

[74] Dajudaju enikeni ti o ba wa ba Oluwa re ni (ipo) elese, dajudaju ina Jahanamo ti wa fun un. Ko nii ku sinu re, ko si nii wa laaye

[75] Enikeni ti o ba si wa ba A (gege bi) onigbagbo ododo, ti o si ti se ise rere, awon wonyen ni awon ipo giga n be fun

[76] (Ohun ni) awon Ogba Idera gbere ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni esan fun enikeni ti o ba safomo (ise re)

[77] Ati pe dajudaju A ti fi imisi ranse si (Anabi) Musa bayii pe: “Mu awon erusin Mi rin ni oru. Fi (opa re) na omi fun won (ki o di) oju ona gbigbe ninu omi okun. Ma se beru aleba, ma si se paya (iteri sinu omi okun).”

[78] Fir‘aon si tele won pelu awon omo ogun re. Ohun ti o bo won mole daru ninu agbami odo si bo won mole daru

[79] Fir‘aon si awon eniyan re lona; oun (naa) ko si mona

[80] Eyin omo ’Isro’il, dajudaju A ti gba yin la lowo ota yin. A si ba yin se adehun egbe otun apata. A si so ohun mimu monu ati ohun jije salwa kale fun yin

[81] E je ninu awon nnkan daadaa ti A pa lese fun yin. E ma si koja enu ala ninu re nitori ki ibinu Mi ma baa ko le yin lori. Enikeni ti ibinu Mi ba si ko le lori, dajudaju o ti jabo (sinu iparun)

[82] Dajudaju Emi ni Alaforijin fun enikeni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, leyin naa ti o tun tele imona

[83] Ki ni o mu o kanju ya awon eniyan re sile, Musa

[84] O so pe: “Awon niwonyi ti won n to oripa mi bo (leyin mi). Emi si kanju wa sodo Re nitori ki O le yonu si mi ni, Oluwa mi.”

[85] (Allahu) so pe: "Dajudaju Awa ti dan ijo re wo leyin re. Ati pe Samiriy si won lona

[86] (Anabi) Musa si pada sodo ijo re pelu ibinu ati ibanuje. O so pe: "Eyin ijo mi, se Oluwa yin ko ti ba yin se adehun daadaa ni? Se adehun ti pe ju loju yin ni tabi e fe ki ibinu ko le yin lori lati odo Oluwa yin ni e fi yapa adehun mi

[87] Won wi pe: “Awa ko finnufindo yapa adehun funra wa, sugbon won di eru oso awon eniyan (Misro) ru wa lorun. A si ju u sinu ina (pelu ase Samiriyy). Bayen naa si ni Samiriyy se ju tire.”

[88] O si (fi mo) omo maalu oborogidi kan jade fun won, t’o n dun (bii maalu). Won si wi pe: "Eyi ni olohun yin ati olohun Musa. Amo o ti gbagbe (re)

[89] Se won ko ri i pe ko le da esi oro kan pada fun won ni, ko si ni agbara lati ko inira tabi anfaani kan ba won

[90] Ati pe dajudaju Harun ti so fun won siwaju pe: “Eyin ijo mi, won kan fi se adanwo fun yin ni. Dajudaju Oluwa yin ni Ajoke-aye. Nitori naa, e tele mi. Ki e si tele ase mi.”

[91] Won wi pe: “A o nii ye duro sodo re titi (Anabi) Musa yoo fi pada sodo wa.”

[92] (Anabi) Musa so pe: "Harun, ki ni o ko fun o nigba ti o ri won ti won sina

[93] lati to mi wa? Se o yapa ase mi ni

[94] (Anabi Harun) so pe: “Omo iya mi, ma se fi irungbon mi tabi ori mi fa mi (mora). Dajudaju emi paya pe o maa so pe: 'O da opinya sile laaarin awon omo ’Isro’il. O o si so oro mi

[95] (Anabi Musa) so pe: “Ki ni oro tire ti je, Samiriyy?”

[96] (Samiriyy) wi pe: “Mo ri ohun ti won ko ri. Mo si bu ekunwo kan nibi (erupe) oju ese (esin) Ojise (iyen, molaika Jibril). Mo si da a sile (lati fi mo ere). Bayen ni emi mi se (aburu) ni oso fun mi.”

[97] (Anabi Musa) so pe: “Nitori naa, maa lo. Dajudaju (ijiya) re nile aye yii ni ki o maa wi pe, “Ma fi ara kan mi”. Ati pe dajudaju ojo iya kan n be fun o ti Won ko nii gbe fo o. Ki o si wo olohun re, eyi ti o taku ti lorun, dajudaju a maa dana sun un. Leyin naa, dajudaju a maa ku eeru re danu patapata sinu agbami odo

[98] Olohun yin ni Allahu nikan, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O fi imo gbooro ju gbogbo nnkan

[99] Bayen ni A se n so itan fun o ninu awon iro ti o ti siwaju. Lati odo Wa si ni A kuku ti fun o ni iranti (iyen, al-Ƙur’an)

[100] Enikeni ti o ba gbunri kuro nibe, dajudaju o maa ru eru ese ni Ojo Ajinde

[101] Olusegbere ni won ninu (iya) re. (Eru ese) si buru fun won lati ru ni Ojo Ajinde

[102] Ni ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. A si maa ko awon elese jo ni ojo yen, oju won yo si dudu batakun

[103] Won yo si maa soro ni jeeje laaarin ara won pe: "Eyin ko gbe ile aye tayo (ojo) mewaa

[104] Awa nimo julo nipa ohun ti won n wi nigba ti eni-abiyi julo ninu won wi pe: “E ko gbe ile aye tayo ojo kan.”

[105] Won n bi o leere nipa awon apata. So pe: “Oluwa mi yoo ku won danu tan raurau

[106] Nigba naa, O maa fi won sile ni petele gbansasa

[107] O o si nii ri ogbun tabi gelemo kan ninu re

[108] Ni ojo yen, awon eniyan yoo tele olupepe naa, ko nii si yiya kuro leyin re. Awon ohun yo si palolo fun Ajoke-aye. Nitori naa, o o nii gbo ohun kan bi ko se girigiri ese

[109] Ni ojo yen, isipe ko nii se anfaani afi eni ti Ajoke-aye ba yonda fun, ti O si yonu si oro fun un

[110] (Allahu) mo ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be ni eyin won. Awon ko si fi imo rokiri ka Re

[111] Awon oju yo si wole fun Alaaye, Alamojuuto-eda. Dajudaju enikeni ti o ba di abosi meru ti pofo

[112] Enikeni ti o ba se ninu awon ise rere, ti o si je onigbagbo ododo, ki o ma se paya abosi tabi ireje kan (lati odo Allahu)

[113] Bayen ni A se so (iranti) kale ni ohun kike pelu ede Larubawa. A si se alaye oniran-anran ileri sinu re nitori ki won le sora (fun iya) tabi nitori ki o le je iranti fun won

[114] Nitori naa, Allahu Oba Ododo ga julo. Ma se kanju pelu al-Ƙur’an siwaju ki won to pari imisi re fun o. Ki o si so pe: “Oluwa mi, salekun imo fun mi.”

[115] Dajudaju A se adehun fun (Anabi) Adam siwaju. Sugbon o gbagbe. A ko si ba a pelu ipinnu okan

[116] Nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki Adam. Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, (ti) o ko.”

[117] Nitori naa, A so pe: "Adam, dajudaju eyi ni ota fun iwo ati iyawo re. Nitori naa, ko gbodo mu eyin mejeeji jade kuro ninu Ogba Idera nitori ki o ma baa daamu (fun ije-imu)

[118] Dajudaju ebi ko nii pa o, o o si nii rin hoho ninu re

[119] Ati pe dajudaju ongbe ko nii gbe o ninu re, oorun ko si nii pa o

[120] Sugbon Esu ko royiroyi ba a; o wi pe: “Adam, nje mo le juwe re si igi gbere ati ijoba ti ko nii tan?”

[121] Nitori naa, awon mejeeji je ninu (eso) re. Ihoho awon mejeeji si han sira won; awon mejeeji si bere si da ewe Ogba Idera bo ara won. Adam yapa ase Oluwa re. O si sina

[122] Leyin naa, Oluwa re sa a lesa; O gba ironupiwada re, O si to o si ona

[123] (Allahu) so pe: "Eyin mejeeji, e jade kuro ninu re patapata. Apa kan yin si je ota si apa kan - eyin ati Esu. Nigba ti imona ba si de ba yin lati odo Mi, enikeni ti o ba tele imona Mi, ko nii sina, ko si nii daamu

[124] Enikeni ti o ba si seri kuro nibi iranti Mi, dajudaju isemi inira maa wa fun un nile aye. A si maa gbe e dide ni afoju ni Ojo Ajinde.”

[125] (O) maa wi pe: “Oluwa mi, nitori ki ni O fi gbe mi dide ni afoju? Mo ti je oluriran tele!”

[126] (Allahu) so pe: "Bayen ni awon ayah Wa se de ba o, o si gbagbe re (o pa a ti). Ni oni, bayen ni won se maa gbagbe iwo naa (sinu Ina)

[127] Ati pe bayen ni A se n san esan fun enikeni ti o ba se aseju, ti ko si gbagbo ninu awon ayah Oluwa re. Dajudaju iya Ojo Ikeyin le julo. O si maa wa titi laelae

[128] Se ko han si won pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti parun siwaju won, ti (awon wonyi naa) si n rin koja ni ibugbe won! Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon oloye

[129] Ti ko ba je pe oro kan t’o siwaju ati gbedeke akoko kan lodo Oluwa re (iya ese won) iba ti di dandan

[130] Nitori naa, se suuru lori ohun ti won n wi, ki o si se afomo pelu ope fun Oluwa Re siwaju yiyo oorun ati siwaju wiwo re. Se afomo (fun Allahu) ni awon asiko ale ati ni awon abala osan, ki o reti (esan) ti o maa yonu si

[131] Ma se feju re si ohun ti A fi se igbadun t’o je ododo isemi ile aye fun awon iran-iran kan ninu won. (A fun won) nitori ki A le fi se adanwo fun won ni. Arisiki Oluwa re loore julo. O si maa wa titi laelae

[132] Pa ara ile re lase irun kiki, ki o si se suuru lori re. A o nii beere ese kan lowo re; Awa l’A n pese fun o. Igbeyin rere si wa fun iberu (Allahu)

[133] Won wi pe: “Nitori ki ni ko fi mu ami kan wa fun wa lati odo Oluwa re?” Se eri t’o yanju t’o wa ninu awon takada akoko ko de ba won ni

[134] Ti o ba je pe dajudaju A ti fi iya kan pa won run siwaju re ni, won iba wi pe: "Oluwa wa nitori ki ni O o se ran Ojise kan si wa, awa iba tele awon ayah Re siwaju ki a to yepere, (ki a si to) kabuku

[135] So pe: “Eni kookan ni olureti (ikangun).” Nitori naa, e maa reti (re). E maa mo ta ni ero ona taara ati eni t’o mona

Àwọn Wòlíì

Surah 21

[1] Isiro-ise sunmo fun awon eniyan, won si wa ninu ifonufora, ti won n gbunri (kuro nibi ododo)

[2] Ko si iranti titun kan ti o maa de ba won lati odo Oluwa won afi ki won gbo o pelu ere sise

[3] Won fonufora ni. Awon t’o sabosi si fi oro ikoko (aarin ara won) pamo pe: "Se eyi tayo abara bi iru yin ni? Se e maa tele idan ni, nigba ti eyin naa riran

[4] O so pe: “Oluwa mi mo oro t’o n be ninu sanmo ati ile. Oun ni Olugbo, Onimo.”

[5] Rara, won tun wi pe: “Awon ala ti itumo re lopo mora won ni (al-Ƙur’an.” Won tun wi pe): “Rara, o hun un ni.” (Won tun wi pe): “Rara, elewi ni. Bi bee ko ki o mu ami kan wa fun wa gege bi won se fi ran awon eni akoko.”

[6] Ko si awon t’o gbagbo siwaju won ninu awon ilu ti A ti pare (leyin isokale ami). Se awon si maa gbagbo (nigba ti ami ba de)

[7] A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si. Nitori naa, e beere lodo awon oniran-anti ti eyin ko ba mo

[8] A ko si se won ni abara ti ko nii jeun. Won ko si je olusegbere (nile aye). abara ni ki i se olohun. Allahu awon oku ko le gbo oro kan kan mo lati odo awon alaaye ni ibamu si surah an-Naml; 27:80 surah ar-Rum; 30:52 ati surah Fatir; 35:22. Anabi wa Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) si pada di oku ti won bo mo inu saree ninu ilu Modinah Onimoole ni ibamu si surah az-Zumor; 39:30. Ko si si ayah taara kan ninu al-Ƙur’an ti o yo Anabi wa Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) sile ninu awon oku ti ko le gbo oro kan kan mo lati odo awon alaaye. Amo hadith t’o fese rinle wa ti o n fi rinle pe “Ko si eni kan ti o maa salamo si mi afi ki Allahu da emi mi pada si mi lara titi mo maa fi da salamo naa pada fun un.” Abu Daud l’o gba a wa labe akole: bab ziyaratul-ƙubur. Seek al-Baniy so pe “hadith naa dara”. Hadith yii tun wa ninu musnad ’Ahmad ati sunan Baehaƙiy. Ojise Allahu (sollalahu 'alayhi wa sallam) so pe “Dajudaju ojo Jum‘ah wa ninu awon ojo yin t’o loore julo; Won seda Anabi Adam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ninu re ni isele t’o tayo oye wa amo ti o tenu Anabi wa Muhammad olododo (sollalahu 'alayhi wa sallam) jade ti o si dari yin pelu ohun ti n be lodo yin.” Eni kan ninu awon t’o gba hadith yii wa so pe “Ki ni itumo “ti o si dari yin pelu ohun ti n be lodo yin”? Tabi ki ni itumo “ti ohun ti o maa fi dari yin si maa wa lati odo yin?” Ibnu Abi Thanb si fesi pe

[9] Leyin naa, A mu adehun Wa se fun won. A si gba awon Ojise ati awon ti A ba fe la. A si pa awon olutayo enu-ala run

[10] Dajudaju A ti so tira kan kale fun yin, ti iranti nipa oro ara yin wa ninu re. Nitori naa, se e o se laakaye ni

[11] Meloo meloo ninu ilu ti A ti pare, ti o je alabosi! A si gbe awon ijo miiran dide leyin won

[12] Nigba ti won ri iya Wa (t’o n bo), won si n sa lo fun un

[13] E ma se sa lo. E pada sibi nnkan ti A fi se gbedemuke fun yin ati awon ibugbe yin nitori ki A le bi yin ni ibeere

[14] Won wi pe: “Egbe wa o! Dajudaju awa je alabosi.”

[15] Igbe won yii ko duro titi A fi so won di koriko ti won ge, won si doku kale

[16] Awa ko da sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin awon mejeeji pelu ere sise

[17] Ti o ba je pe A gbero lati sere ni, odo Wa ni A kuku ti maa se e ti A ba je oluse-(ere)

[18] Rara o! A n so ododo lu iro (mole ni). Ododo si maa fo agbari iro. Iro si maa poora. Egbe si ni fun yin nipa ohun ti e n fi royin (Re ni ti iro)

[19] TiRe ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Ati pe awon t’o n be lodo Re, won ki i segberaga nibi ijosin Re. Ati pe won ko kole

[20] Won n safomo ni oru ati ni osan; ko si re won

[21] Tabi won ni awon olohun kan ti won mu jade lati ara ile, ti won n ji oku dide ni

[22] Ti o ba je pe awon olohun kan wa ninu sanmo ati ile leyin Allahu, sanmo ati ile iba ti baje. Mimo ni fun Allahu, Oluwa Ite-ola, tayo ohun ti won n fi royin (Re)

[23] Won ko nii bi (Allahu) ni ibeere nipa nnkan ti O n se. Awon ni won maa bi ni ibeere (nipa ise owo won)

[24] Tabi won so awon kan di olohun leyin Allahu ni? So pe: “E mu eri oro yin wa.” (Al-Ƙur’an) yii ni iranti nipa awon t’o wa pelu mi ati iranti nipa awon t’o siwaju mi. Sugbon opolopo won ko mo ododo; won si n gbunri kuro nibe

[25] A ko ran ojise kan nise siwaju re afi ki A fi imisi ranse si i pe: “Dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Emi (Allahu). Nitori naa, e josin fun Mi.”

[26] Won wi pe: “Ajoke-aye so eni kan di omo.” Mimo ni fun Un – Ko ri bee; erusin alapon-onle ni won

[27] Won ki i siwaju Allahu soro. Won si n sise pelu ase Re

[28] (Allahu) mo ohun t’o n be niwaju won ati ohun t’o n be leyin won. Won ko si nii sipe (eni kan) afi eni ti (Allahu) ba yonu si. Won tun n paya fun iberu Re

[29] Ati pe enikeni ninu won ti o ba wi pe: “Dajudaju emi ni olohun leyin Re.” Nitori iyen si ni A oo fi san an ni esan ina Jahanamo. Bayen si ni A se n san awon alabosi ni esan

[30] Se awon t’o sai gbagbo ko ri i pe dajudaju awon sanmo le po ati ile naa le po tele ni, A si ya won si otooto, A si se gbogbo nnkan ni abemi lati inu omi? Nitori naa, se won ko nii gbagbo ni? lile-papo” itumo “fatƙ” si ni “ela

[31] A si fi awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ki o ma fi le mi mo won lese. A si fi awon ona fife saaarin awon apata nitori ki won le ri ona to

[32] A tun se sanmo ni aja ti won n so (nibi jijabo). Sibesibe won n gbunri kuro nibi awon ami re

[33] Oun ni Eni ti O da oru ati osan pelu oorun ati osupa. Ikookan (oorun ati osupa) wa ni opopona roboto t’o n to

[34] A ko se bibe gbere fun abara kan siwaju re. Nje ti o ba ku, awon si ni olusegbere bi

[35] Emi kookan l’o maa to iku wo. A si maa fi aburu ati rere sadanwo fun yin. Odo Wa si ni won yoo da yin pada si

[36] Nigba ti awon t’o sai gbagbo ba ri o, won ko si nii ka o kun kini kan bi ko se oniyeye pe: “Se eyi ni eni t’o n soro nipa awon olohun yin?” Alaigbagbo si ni awon naa nipa iranti Ajoke-aye

[37] Won fi ikanju se eniyan. Mo maa fi awon ami Mi han yin. Nitori naa, e ma se kan Mi loju

[38] Won si n wi pe: “Igba wo ni ileri yii yoo se na, ti e ba je olododo?”

[39] Ti o ba je pe awon t’o sai gbagbo mo igba ti won ko nii da Ina duro niwaju won ati ni eyin won, ti A o si nii ran won lowo, (won iba ti wa iya pelu ikanju)

[40] Sugbon (iya Ina) yoo ba won ni ojiji, nigba naa o maa ko idaamu ba won; won ko si nii le da a pada. A o si nii sun (iya naa) siwaju fun won

[41] Won kuku ti fi awon Ojise kan se yeye siwaju re! Nitori naa, ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi awon t’o n fi won se yeye po

[42] So pe: "Ta ni eni ti o n so yin ni oru ati ni osan nibi iya Ajoke-aye?" Amo nse ni won n gbunri kuro nibi iranti Ajoke-aye

[43] Tabi won ni awon olohun kan t’o maa gba won sile leyin Wa ni? Won ko le ran ara won lowo. Won ko si le gba won sile lodo Wa

[44] Bee ni, A fun awon wonyi ati awon baba won ni igbadun titi isemi aye won fi gun. Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A n mu ile dinku (mo awon alaigbagbo lowo) lati awon eti ilu (wonu ilu nipa fifun awon musulumi ni isegun lori won). Nitori naa, se awon ni olubori ni

[45] So pe: “Imisi ni mo fi n kilo fun yin. Awon aditi ko si nii gbo ipe nigba ti won ba n kilo fun won.”

[46] Ati pe dajudaju ti abala kan ninu iya Oluwa re ba fowo ba won, dajudaju won a wi pe: “Egbe wa o; dajudaju awa je alabosi.”

[47] A maa gbe awon osuwon deede kale ni Ojo Ajinde. Nitori naa, won ko nii se abosi kini kan fun emi kan. Ki (ise) je iwon eso kardal (bin-intin), A maa mu un wa. A si to ni Olusiro

[48] Dajudaju A fun (Anabi) Musa ati (Anabi) Harun ni oro-ipinya (ohun t’o n sopinya laaarin ododo ati iro), imole ati iranti fun awon oluberu (Allahu)

[49] (Awon ni) awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko. Olupaya si ni won nipa Akoko naa

[50] Eyi si ni iranti onibukun ti A sokale. Se eyin yoo tako o ni

[51] Dajudaju A ti fun (Anabi) ’Ibrohim ni imona tire siwaju (ki o to dagba). Awa si n je Onimo nipa re

[52] (Ranti) nigba ti o so fun baba re ati ijo re pe: “Ki ni awon ere wonyi ti e n duro ti lorun se je na?”

[53] Won wi pe: “A ba awon baba wa ti won n josin fun won ni.”

[54] O so pe: “Dajudaju eyin ati awon baba yin ti wa ninu isina ponnbele.”

[55] Won wi pe: “Se o mu ododo wa fun wa ni tabi iwo wa lara awon elefe.”

[56] O so pe: "Rara. Oluwa yin ni Oluwa awon sanmo ati ile; Eni ti O pile iseda won. Emi si wa ninu awon elerii lori iyen

[57] Ati pe mo fi Allahu bura, dajudaju mo maa dete si awon orisa yin leyin ti e ba peyin da, ti e lo

[58] O si fo won si wewe afi agba (orisa) won nitori ki won le pada de ba a

[59] Won wi pe: “Ta ni o se eyi pelu awon olohun wa? Dajudaju onitoun wa ninu awon alabosi.”

[60] Won wi pe: “A gbo ti odokunrin kan n bu enu ate lu won. Won n pe (omo naa) ni ’Ibrohim.”

[61] Won wi pe: “E mu un wa han awon eniyan ki won le jerii le e lori.”

[62] Won wi pe: “Se iwo l’o se eyi pelu awon olohun wa, ’Ibrohim?”

[63] O so pe: “Rara o, agba won yii l’o se (won bee). Nitori naa, e bi won leere wo ti won ba maa n soro.”

[64] Nigba naa, won yiju sira won, won si wi pe: “Dajudaju eyin ni alabosi.”

[65] Leyin naa, won sori ko (won si wi pe): “Iwo naa kuku mo pe awon wonyi ki i soro.”

[66] O so pe: "Se eyin yoo maa josin fun nnkan ti ko le se yin ni anfaani, ti ko si le ko inira ba yin leyin Allahu

[67] Sio eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu, se eyin ko nii se laakaye ni

[68] Won wi pe: “E dana sun un; ki e si ran awon olohun yin lowo, ti eyin ba nikan-an se.”

[69] A so pe: “Ina, di tutu ati alaafia lara ’Ibrohim.”

[70] Won gbero ete si i, sugbon A se won ni olofo julo

[71] A si gba oun ati Lut la sori ile ti A fi ibukun si fun gbogbo eda

[72] A ta a ni ore omo, ’Is-haƙ ati Ya‘ƙub ti o je alekun (iyen, omoomo). Olukuluku (won) ni A se ni eni rere

[73] A se won ni asiwaju t’o n to awon eniyan si ona pelu ase Wa. A si fi imisi ranse si won nipa sise ise rere, irun kiki ati Zakah yiyo. Won si je olujosin fun Wa

[74] (E ranti Anabi) Lut. A fun un ni ipo Anabi ati imo. A si gba a la ninu ilu ti won ti n se awon ise buruku. Dajudaju won je ijo buruku, obileje

[75] A si mu un wo inu ike Wa. Dajudaju o wa ninu awon eni rere

[76] (E ranti Anabi) Nuh, nigba ti o pe ipe siwaju (yin). A si da a lohun. A si gba oun ati awon eniyan re la ninu ibanuje nla

[77] A si saranse fun un lori awon eniyan t’o pe awon ayah Wa niro. Dajudaju won je ijo buruku. A si te won ri patapata

[78] (E ranti Anabi) Dawud ati (Anabi) Sulaemon, nigba ti awon mejeeji n se idajo lori (oro) oko, nigba ti agutan ijo kan jeko wo inu oko naa. Awa si je Olujerii si idajo won

[79] A si fun (Anabi) Sulaemon ni agboye re. Ati pe ikookan (won) ni A fun ni ipo Anabi ati imo. A si te awon apata ati eye ba; won n se afomo (fun Allahu) pelu (Anabi) Dawud. Awa l’A se won bee

[80] A tun fun un ni imo nipa sise ewu irin fun yin nitori ki o le je odi iso fun yin nibi ogun yin. Nitori naa, nje oludupe (fun Allahu) ni eyin bi

[81] A si te ategun lile lori ba fun (Anabi) Sulaemon. O n gbe e lo pelu ase re sori ile ti A fi ibukun si. A si n je Onimo nipa gbogbo nnkan

[82] Ninu awon esu, awon t’o n wa kusa okun tun wa fun un. Won tun n se ise miiran yato si iyen. Awa si n je Oluso fun won

[83] (E ranti Anabi) ’Ayyub, nigba ti o pe Oluwa re pe: "Dajudaju owo inira ti kan mi. Iwo si ni Alaaanu julo ninu awon alaaanu

[84] A si je ipe re. A mu gbogbo inira re kuro fun un. A tun fun un ni awon ebi re (pada) ati iru won pelu won; (o je) ike lati odo Wa ati iranti fun awon olujosin (fun Wa)

[85] (E ranti Anabi) ’Ismo‘il ati (Anabi) ’Idris ati (Anabi) Thul-Kifl; eni kookan (won) wa ninu awon onisuuru

[86] A si fi won sinu ike Wa. Dajudaju won wa ninu awon eni rere

[87] (E ranti) eleja, nigba ti o ba ibinu lo, o si lero pe A o nii gba oun mu. O si pe (Oluwa re) ninu awon okunkun (inu eja) pe: "Ko si olohun ti ijosin to si afi Iwo (Allahu). Mimo ni fun O. Dajudaju emi je okan ninu awon alabosi

[88] A je ipe re. A si gba a la ninu ibanuje. Bayen ni A se n gba awon onigbagbo ododo la

[89] (E ranti Anabi) Zakariyya nigba ti o pe Oluwa re pe: “Oluwa mi, ma fi mi sile ni emi nikan (ti ko nii bimo). Iwo si loore julo ninu awon olujogun.”

[90] A je ipe re. A si ta a lore omo, (Anabi) Yahya. A si se atunse iyawo re fun un. Dajudaju won n yara gaga nibi awon ise rere. Won n pe Wa pelu ireti ati ipaya. Won si je oluteriba fun Wa

[91] (E ranti obinrin) eyi ti o so abe re. A si fe ategun ninu awon ategun emi ti A da si i lara. A si se oun ati omokunrin re ni ami fun gbogbo eda

[92] Dajudaju (’Islam) yii ni esin yin. (O je) esin kan soso. Emi si ni Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Mi

[93] (Awon yehudi ati nasara), won si da oro (esin) won si kelekele laaarin ara won; eni kookan (won) si maa pada si odo Wa

[94] Nitori naa, enikeni ti o ba se ninu awon ise rere, ti o si je onigbagbo ododo, ko si kiko fun ise re. Ati pe dajudaju Awa maa se akosile re fun un

[95] Eewo ni fun ara ilu kan ti A ti pare (pe ki o tun pada si aye); dajudaju won ko nii pada mo (si ile aye)

[96] (Won yoo wa ninu barsaku) titi A oo fi si awon Ya’juj ati Ma’juj sile. Awon (wonyi) yo si maa sare jade lati inu gbogbo aye giga

[97] Adehun ododo naa sunmo pekipeki. Nigba naa, awon t’o sai gbagbo yoo maa ranju kale rangandan, (won yo si wi pe): “Egbe ni fun wa! Dajudaju awa ti wa ninu igbagbera nipa eyi. Rara, awa je alabosi ni.”

[98] Dajudaju eyin ati nnkan ti e n josin fun leyin Allahu ni ikona Jahanamo; eyin yo si wo inu re

[99] Ti o ba je pe awon wonyi ni olohun ni, won iba ti wo inu Ina. Olusegbere si ni eni kookan won ninu re

[100] Ina yoo maa kun yun-un si won leti; won ko si nii gbo (oro miiran)

[101] Dajudaju awon ti rere ti siwaju fun lati odo Wa, awon wonyen ni A oo gbe jinna si Ina

[102] Won ko si nii gbo kikun re. Olusegbere si ni won ninu igbadun ti emi won n fe

[103] Ipaya t’o tobi julo ko nii ba won ninu je. Awon molaika yoo maa pade won, (won yoo so pe): “Eyi ni ojo yin ti A n se ni adehun fun yin.”

[104] (Ojo naa ni) ojo ti A maa ka sanmo bi kika ewe tira. Gege bi A ti se bere iseda eda ni ibere pepe (ibe naa ni) A oo da a pada si. (O je) adehun ti A se. Dajudaju Awa maa se bee

[105] Ati pe A ti ko o sinu awon ipin-ipin Tira (ti A sokale) leyin (eyi ti o wa ninu) Tira Ipile (iyen, Laohul-Mahfuth) pe dajudaju ile (Ogba Idera), awon erusin Mi, awon eni rere, ni won yoo jogun re

[106] Dajudaju ohun t’o to mu ni gunle sinu Ogba Idera ti wa ninu (al-Ƙur’an) yii fun ijo olujosin (fun Mi)

[107] A ko si fi ise imisi ran o bi ko se pe ki o le je ike fun gbogbo eda

[108] So pe: “Ohun ti Won n fi ranse si mi ni imisi ni pe, Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, se eyin maa di musulumi?”

[109] Ti won ba gbunri, so nigba naa pe: "Emi n fi to yin leti pe emi ati eyin di jo da duro fun ogun esin (ti o maa sele laaarin wa bayii). Emi ko si mo boya ohun ti Won n se ni adehun fun yin ti sunmo tabi o si jinna

[110] Dajudaju (Allahu) mo ohun ti o han ninu oro. O si mo ohun ti e n fi pamo

[111] Emi ko si mo boya (lilo yin lara) maa je adanwo ati igbadun fun yin titi di igba die

[112] O so pe: “Oluwa mi, sedajo pelu ododo. Oluwa wa ni Ajoke-aye, Oluranlowo lori ohun ti e n fi royin (Re).”

Ìrìnàjò Hajj

Surah 22

[1] Eyin eniyan, e beru Oluwa yin. Dajudaju imi titi Akoko naa, nnkan nla ni

[2] (Akoko naa ni) ojo ti e maa ri i ti gbogbo obinrin t’o n fun omo lomu mu yoo gbagbe omo ti won n fun lomu ati pe gbogbo aboyun yo si maa bi oyun won. Iwo yo si ri awon eniyan ti oti yoo maa pa won. Oti ko si pa won, sugbon iya Allahu (t’o) le (l’o fa a)

[3] O si n be ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa (esin) Allahu lai ni imo. O si n tele gbogbo esu olori kunkun

[4] Won ko o le (Esu) lori pe dajudaju enikeni ti o ba tele e, o maa si i lona. O si maa to o si ona iya Ina t’o n jo fofo

[5] Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa ajinde, dajudaju Awa seda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa lati inu baasi eran ti o pe ni eda ati eyi ti ko pe ni eda nitori ki A le salaye (agbara Wa) fun yin. A si n mu ohun ti A ba fe duro sinu apo ibimo titi di gbedeke akoko kan. Leyin naa, A oo mu yin jade ni oponlo. Leyin naa, (e oo maa semi lo) nitori ki e le sanngun dopin agbara yin. Eni ti o maa ku (ni kekere) wa ninu yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da (isemi) re si di asiko ogbo kujokujo nitori ki o ma le mo nnkan kan mo leyin ti o ti mo on. Ati pe o maa ri ile ni gbigbe. Nigba ti A ba si so ojo kale le e lori, o maa yira pada. O maa gberu. O si maa mu gbogbo orisirisi irugbin t’o dara jade

[6] Iyen nitori pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Dajudaju Oun l’O n so awon oku di alaaye. Dajudaju Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[7] Ati pe dajudaju Akoko naa n bo. Ko si iyemeji ninu re. Dajudaju Allahu yoo gbe awon t’o n be ninu saree dide

[8] O n be ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa (esin) Allahu lai ni imo (al-Ƙur’an) ati imona (sunnah Anabi) ati tira (onimo-esin) t’o n tan imole (soro esin)

[9] O n yi orun re ka ni ti igberaga nitori ki o le ko isina ba awon eniyan loju ona (esin) Allahu. Abuku n be fun un nile aye. Ni Ojo Ajinde, A si maa fun un ni iya Ina jonijoni to wo

[10] Iyen nitori ohun ti owo re ti siwaju. Dajudaju Allahu ko nii sabosi si awon erusin Re

[11] O tun wa ninu awon eniyan eni t’o n josin fun Allahu lori ahon. Ti rere ba sele si i, o maa fi okan bale (sinu esin). Ti ifooro ba si sele si i, o maa yiju re pada kuro ninu esin. O sofo laye ati lorun. Iyen ni ofo ponnbele

[12] O n pe leyin Allahu ohun ti ko le ko inira ba a, ti ko si le se e ni oore; iyen ni isina t’o jinna (si imona)

[13] O n pe ohun ti inira re sunmo ju anfaani re lo. Dajudaju (orisa) buru ni oluranlowo, o si buru ni alasun-unmo

[14] Dajudaju Allahu yoo mu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re. Dajudaju Allahu n se ohun ti O ba fe

[15] Enikeni ti o ba lero pe Allahu ko nii ran (Anabi) lowo laye ati lorun, ki o na okun si sanmo leyin naa ki o ge e (iyen ni pe, ki o pokun so). Ki o wo o nigba naa boya ete re le mu (aranse) t’o n binu si kuro (lodo Anabi s.a.w)

[16] Bayen ni A se so o kale ni awon ayah t’o yanju. Dajudaju Allahu n to eni ti O ba fe si ona

[17] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo ati awon t’o di yehudi, awon sobi’un, awon kristieni, awon mojus ati awon t’o sebo, dajudaju Allahu yoo sedajo laaarin won ni Ojo Ajinde. Dajudaju Allahu ni Arinu-rode gbogbo nnkan

[18] Se o o ri i pe dajudaju Allahu ni awon t’o n be ninu awon sanmo ati awon t’o n be lori ile, ati oorun, osupa, awon irawo, awon apata, awon igi, awon nnkan elemii ati opolopo ninu awon eniyan n fori kanle fun? Opolopo si tun ni iya ti ko le lori. Enikeni ti Allahu ba fi abuku kan, ko si eni kan ti o maa se aponle re. Dajudaju Allahu n se ohun ti O ba fe

[19] Awon onija meji (kan) niyi, won n tako ara won nipa Oluwa won. Nitori naa, awon t’o sai gbagbo, won maa ge aso Ina fun won, won si maa da omi gbigbona le won lori lati oke ori won

[20] Won maa fi yo ohun ti n be ninu ikun won ati awo ara won

[21] Awon oduro irin (iya) si wa fun won pelu

[22] Igbakigba ti won ba fe jade kuro ninu re latara ibanuje, won a da won pada sinu re. (A oo so pe): “E to iya Ina jonijoni wo.”

[23] Dajudaju Allahu yoo fi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. A oo se won ni oso ninu re pelu egba wura ati aluuluu. Aso alaari si ni aso won ninu re

[24] A fun won ni imona sibi ohun t’o dara ninu oro. A si to won si ona Eleyin

[25] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu ati Mosalasi Haram, eyi ti A se ni dogbadogba fun awon eniyan, olugbe-inu re ati alejo (fun ijosin sise), enikeni ti o ba ni ero lati se iyipada kan nibe pelu abosi, A maa mu un to iya eleta-elero wo

[26] (E ranti) nigba ti A safi han aye ile naa fun (Anabi) ’Ibrohim (A si pa a lase) pe o o gbodo so kini kan di akegbe fun Mi. Ati pe ki o se ile Mi ni mimo fun awon oluyipo re, olukirun, oludawote-orunkun ati oluforikanle

[27] Ki o si pe ipe fun awon eniyan fun ise Hajj. Won yoo wa ba o pelu irin ese. Won yo si maa gun awon rakunmi wa lati awon ona jijin

[28] nitori ki won le ri awon anfaani t’o n be fun won ati nitori ki won le seranti oruko Allahu fun awon ojo ti won ti mo lori nnkan ti Allahu pa lese fun won ninu awon eran-osin. Nitori naa, e je ninu re, ki e si fi bo alailera, talika

[29] Leyin naa, ki won pari ise Hajj won, ki won mu awon eje won se, ki won si yipo Ile Laelae

[30] Iyen (niyen). Enikeni ti o ba si pataki awon nnkan ti Allahu fi se arisami fun esin ’Islam, o loore julo fun un lodo Oluwa re. Won si se awon eran-osin ni eto fun yin ayafi awon ti won n ka (ni eewo) fun yin. Nitori naa, e jinna si egbin orisa. Ki e si jinna si oro iro

[31] (E je) oluduro-deede-ninu-esin fun Allahu, lai nii je osebo si I. Enikeni ti o ba sebo si Allahu, o da bi eni t’o jabo lati oju sanmo, ti eye si gbe e lo tabi (ti) ategun ju u sinu aye t’o jinna

[32] Iyen (niyen). Enikeni ti o ba si pataki awon nnkan ti Allahu fi se arisami fun esin ’Islam, dajudaju o wa lara nini iberu Allahu ninu okan

[33] Awon anfaani wa fun yin lara awon eran-osin titi di gbedeke akoko kan. Leyin naa, Ile Laelae ni ibupa awon eran naa

[34] Ikookan ijo (musulumi t’o siwaju) ni A yan eran pipa fun nitori ki won le daruko Allahu lori ohun ti O pese fun won ninu awon eran-osin. Nitori naa, Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Oun ni ki e je musulumi fun. Ki o si fun awon olokan irele, awon olufokanbale sodo Allahu ni iro idunnu

[35] (Awon ni) awon ti o je pe ti A ba daruko Allahu (fun won), okan won maa gbon riri. (Won je) onisuuru lori ohun ti o ba sele si won. (Won je) olukirun. Won si n na ninu ohun ti A pa lese fun won

[36] Awon rakunmi, A se won ninu awon nnkan arisami fun esin Allahu fun yin. Oore wa lara won fun yin. Nitori naa, e daruko Allahu le won lori (ki e si gun won) ni iduro. Nigba ti won ba fi egbe lele, e je ninu re. E fi bo oniteelorun ati atoroje. Bayen ni A se ro won fun yin nitori ki e le dupe (fun Un)

[37] Eran (ti e pa) ati eje re ko nii de odo Allahu. Sugbon iberu Allahu lati odo yin l’o maa de odo Re. Bayen ni (Allahu) se ro won fun yin nitori ki e le se igbetobi fun Allahu nipa bi O se fi ona mo yin. Ki o si fun awon oluse-rere ni iro idunnu

[38] Dajudaju Allahu n ti aburu kuro fun awon t’o gbagbo ni ododo. Dajudaju Allahu ko nifee gbogbo awon onijanba, alaigbagbo

[39] A yonda (ogun esin jija) fun awon (musulumi) ti (awon keferi) n gbogun ti nitori pe (awon keferi) ti se abosi si won. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori aranse won

[40] (Awon ni) awon ti won le jade kuro ninu ile won ni ona aito afi (nitori pe) won n so pe: “Allahu ni Oluwa wa.” Ti ko ba je pe Allahu n dena (aburu) fun awon eniyan ni, ti O n fi apa kan won dena (aburu) fun apa kan, won iba ti wo ile isin awon fada, soosi, sinagogu ati awon mosalasi ti won ti n daruko Allahu ni opolopo.1 Dajudaju Allahu yoo se aranse fun enikeni t’o n ran (esin ’Islam) Re lowo. Dajudaju Allahu ma ni Alagbara, Olubori

[41] (Awon naa ni) awon ti o je pe ti A ba fun won ni ipo lori ile, won yoo kirun, won yoo yo Zakah, won yoo pase ohun rere, won yo si ko ohun buruku. Ti Allahu si ni ikangun awon oro eda

[42] Ti won ba pe o ni opuro, awon ijo Nuh, ijo ‘Ad ati ijo Thamud kuku ti pe awon Ojise won ni opuro siwaju won

[43] Ati pe ijo ’Ibrohim ati ijo (Anabi) Lut

[44] ati awon ara ilu Modyan (awon naa se bee). Won tun pe (Anabi) Musa ni opuro. Mo si lo awon alaigbagbo lara. Leyin naa, Mo gba won mu. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri

[45] Nitori naa, meloo meloo ninu ilu ti A ti pare nigba ti won je alabosi; awon ile won dawo lule pelu orule re. (Meloo meloo ninu) kannga ti won ti pati (nipase iparun) ati ile peteesi onibiriki (t’o ti dahoro)

[46] Se won ko rin kiri lori ile ki won si ni awon okan ti won maa fi se laakaye tabi awon eti ti won maa fi gboro? Dajudaju awon oju ko fo, sugbon awon okan t’o wa ninu igba-aya l’o n fo

[47] Won si n kan o loju fun iya naa. Allahu ko si nii yapa adehun Re. Dajudaju ojo kan lodo Oluwa re da bi egberun odun ninu ohun ti e n ka (ni onka). Allahu (subhanahu wa ta'ala) n so nipa idi ti iya ko fi tete sokale le awon alaigbagbo lori pe ti Oun ba so fun won pe aaro ola ni ojo iya won (bi apeere) dipo egberun odun. Kiye si i ninu ayah ojo kan elegberun odun o tun le je oke meji aabo odun yala nile yii tabi lojo Ajinde

[48] Meloo meloo ninu ilu ti Mo lo lara, ti won je alabosi. Leyin naa, Mo gba won mu. Odo Mi si ni abo eda

[49] So pe: "Eyin eniyan, emi ma ni olukilo ponnbele fun yin

[50] Nitori naa, awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, aforijin ati arisiki alapon-onle n be fun won

[51] Awon t’o se ise buruku nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni ero inu ina Jehim

[52] A ko ran Ojise kan tabi Anabi kan nise siwaju re afi ki o je pe nigba ti o ba soro, Esu maa ju (nnkan) sinu oro re. Nitori naa, Allahu yoo pa ohun ti Esu n ju sinu re re. Leyin naa, O maa fi ododo awon ayah Re rinle. Allahu si ni Onimo, Ologbon. won ko ni imo oloookan nipa al-Ƙur’an ati hadith sugbon won mo iro funfun balau pa mo esin ’Islam. Ise won yii si se weku oro ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) so nipa won ninu surah al-Baƙorah; 2: 78. eni ti Esu ba n gbenu re soro bi ko je were ti ko se e fi se eri afi hadith eyo kan pere. Iyen ni pe gbogbo hadith t’o n so nipa pe Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) so pe “Iwonyen ni awon eye agba. Ati pe ireti wa ninu isipe ti won maa se.” je hadith t’o le patapata. Amo eyi ti o fese rinle ninu won ko tayo eyi ti o wa ninu sohihu-l-Bukoriy egbawa Bukoriy ti yanju oro naa. Ko si si oro “awon eye agba meta” kan kan ninu re. Nitori naa hadith ko baa le ni igba lori oro kan naa

[53] (Eyi n sele) nitori ki (Allahu) le fi ohun ti Esu n ju (sinu re) se adanwo fun awon ti aisan n be ninu okan won ati awon ti okan won le. Dajudaju awon alabosi si wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo)

[54] (Eyi n sele) nitori ki awon ti A fun ni imo le mo pe dajudaju al- Ƙur’an je ododo lati odo Oluwa re. Nitori naa, won yo si gbagbo ninu re, okan won yo si bale si i. Dajudaju Allahu l’O n fi ese awon t’o gbagbo ni ododo rinle soju ona taara (’Islam)

[55] Awon t’o sai gbagbo ko si nii ye wa ninu iyemeji nipa re titi Akoko naa yoo fi de ba won ni ojiji tabi (titi) iya ojo iparun yoo fi de ba won

[56] Gbogbo ijoba ojo yen n je ti Allahu ti O maa sedajo laaarin won. Nitori naa, awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, (won yoo wa) ninu awon Ogba Idera

[57] Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro; awon wonyen ni iya ti i yepere eda si wa fun

[58] Awon ti won gbe ilu won ju sile nitori esin Allahu, leyin naa, ti won pa won tabi ti won ku; dajudaju Allahu yoo pese fun won ni ipese t’o dara. Dajudaju Allahu, O ma l’oore julo ninu awon olupese

[59] Dajudaju (Allahu) yoo fi won si aye kan ti won yoo yonu si. Dajudaju Allahu ma ni Onimo, Alafarada

[60] Iyen (niyen). Enikeni ti o ba si gbesan iru iya ti won fi je e, leyin naa ti won ba tun sabosi si i, dajudaju Allahu yoo saranse fun un. Dajudaju Allahu ma ni Alamojuukuro, Alaforijin

[61] Iyen nitori pe dajudaju Allahu n fi oru bo inu osan, O si n fi osan bo inu oru. Allahu si ni Olugbo, Oluriran

[62] Iyen nitori pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Ati pe dajudaju ohun ti won n pe leyin Re ni iro. Dajudaju Allahu, Oun ni O ga, O tobi

[63] Se o o ri i pe dajudaju Allahu n so omi kale lati sanmo, ile si maa loraa wa? Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Alamotan

[64] TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Dajudaju Allahu, Oun ma ni Oloro, Olope

[65] Se o o ri i pe dajudaju Allahu ro ohunkohun t’o wa ninu ile fun yin, ati oko oju-omi t’o n rin ninu agbami odo pelu iyonda Re, O n mu sanmo dani ti ko fi jabo ayafi pelu iyonda Re? Dajudaju Allahu ma ni Alaaanu, Onikee fun awon eniyan

[66] Oun si ni Eni t’O se yin ni alaaye, leyin naa O n so yin di oku, leyin naa O maa so yin di alaaye. Dajudaju eniyan ma ni alaimoore

[67] Ijo kookan l’A fun ni ilana ti won maa lo. Nitori naa, ki won ma se ja o niyan nipa oro naa. Ki o si pepe sodo Oluwa re. Dajudaju o kuku wa loju ona taara

[68] Ti won ba si ja o niyan, so nigba naa pe: "Allahu nimo julo nipa ohun ti e n se nise

[69] Allahu maa sedajo laaarin yin ni Ojo Ajinde nipa ohun ti e n yapa enu si

[70] Se o o mo pe dajudaju Allahu l’O mo ohun ti n be ninu sanmo ati ile? Dajudaju (akosile) iyen wa ninu tira kan. Dajudaju iyen rorun fun Allahu

[71] Dipo (ki won josin fun) Allahu, won n josin fun ohun ti (Allahu) ko so eri kan kale fun ati ohun ti ko si imo kan fun won lori re. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi

[72] Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, o maa ri ikoro-oju ninu oju awon t’o sai gbagbo; won yo si fee fowo inira kan awon ti n ke awon ayah Wa fun won. So pe: "Se ki ng fun yin ni iro ohun t’o buru ju iyen? Ina ti Allahu seleri re fun awon t’o sai gbagbo ni. Ikangun naa si buru

[73] Eyin eniyan, Won fi akawe kan lele. Nitori naa, e teti si i. Dajudaju awon ti e n pe leyin Allahu, won ko le da esinsin kan, won ibaa para po lati se bee. Ti esinsin ba si gba kini kan mo won lowo, won ko le gba a pada lowo re. Ole ni eni ti n wa nnkan (lodo orisa) ati (orisa) ti won n wa nnkan lodo re

[74] Won ko bu owo fun Allahu ni owo ti o to si I. Dajudaju Allahu ma ni Alagbara, Olubori

[75] Allahu l’O n sa awon kan lesa (lati je) Ojise ninu awon molaika ati ninu awon eniyan. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran

[76] O mo ohun ti n be niwaju won ati ni eyin won. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

[77] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e dawo te orunkun (lori irun), e fori kanle, e josin fun Oluwa yin, ki e si se rere nitori ki e le jere

[78] E jagun fun esin Allahu ni ona eto ti e le gba jagun fun Un. Oun l’O sa yin lesa, ko si ko idaamu kan kan ba yin ninu esin. (E tele) esin baba yin (Anabi) ’Ibrohim. (Allahu) l’O so yin ni musulumi siwaju (asiko yii) ati ninu (al-Ƙur’an) yii nitori ki Ojise le je elerii fun yin ati nitori ki eyin naa le je elerii fun awon eniyan. Nitori naa, e kirun, e yo Zakah, ki e si ba Allahu duro. Oun ni Alaabo yin. O dara ni Alaabo. O si dara ni Alaranse

Àwọn Onígbàgbọ́ Òdodo

Surah 23

[1] Dajudaju awon onigbagbo ododo ti jere

[2] Awon t’o n paya (Allahu) ninu irun won

[3] ati awon t’o n seri kuro nibi isokuso

[4] ati awon t’o n yo Zakah

[5] ati awon t’o n so abe won

[6] afi ni odo awon iyawo won ati erubinrin won. Dajudaju won ki i se eni eebu (ti won ba sunmo won)

[7] nitori naa, enikeni ti o ba wa omiran (sunmo) leyin iyen, awon wonyen ni awon olutayo enu-ala

[8] ati awon t’o n so agbafipamo won ati adehun won

[9] ati awon t’o n so irun won

[10] awon wonyen ni awon olujogun

[11] awon t’o maa jogun ogba idera Firdaos. Olusegbere ni won ninu re

[12] Dajudaju A ti se eda eniyan lati inu ohun ti A mo jade lati inu erupe amo

[13] Leyin naa, A se e ni ato sinu aye aabo (iyen, ile-omo)

[14] Leyin naa, A so ato di eje didi. Leyin naa, A so eje didi di baasi eran. Leyin naa, A so baasi eran di eegun. Leyin naa, A fi eran bo eegun. Leyin naa, A so o di eda miiran.1 Nitori naa, ibukun ni fun Allahu, Eni t’O dara julo ninu awon eledaa (onise-ona)

[15] Leyin naa, leyin iyen, dajudaju eyin yo si di oku

[16] Leyin naa, dajudaju ni Ojo Ajinde Won maa gbe yin dide

[17] Dajudaju A da awon sanmo meje si oke yin. Awa ko si nii dagunla si awon eda

[18] A n so omi kale lati sanmo niwon niwon. Leyin naa, A n mu un duro sinu ile. Dajudaju Awa kuku lagbara lati mu un lo

[19] Leyin naa, A da awon ogba oko dabinu ati ajara fun yin; opolopo eso wa ninu re fun yin, e si n je ninu re

[20] Ati igi kan t’o n hu jade nibi apata Sina’; o n mu epo ati nnkan isebe jade fun awon t’o n je e

[21] Ati pe dajudaju ariwoye wa fun yin lara awon eran-osin; A n fun yin mu ninu ohun ti o wa ninu ikun won. Awon anfaani opolopo (miiran) tun wa fun yin lara won, e si n je ninu re

[22] E si n ko eru si ori awon eran osin ati oko oju-omi

[23] Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Se e o nii beru (Re) ni?”

[24] Awon olori ti won sai gbagbo ninu awon eniyan re so pe: “Ki ni eyi bi ko se abara kan bi iru yin, ti o fe gbe ajulo fun ara re lori yin. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe (ranse si wa ni), iba so molaika kan kale ni. A ko si gbo eyi ri lodo awon baba wa, awon eni akoko

[25] Ko je kini kan bi ko se okunrin kan ti alujannu n be lara re. Nitori naa, e maa reti (ikangun) re titi di igba kan na.”

[26] (Anabi) Nuh so pe: "Oluwa mi, saranse fun mi nitori pe won pe mi ni opuro

[27] Nitori naa, A fi imisi ranse si i pe: "Se oko oju-omi ni oju Wa (bayii) pelu imisi Wa. Nigba ti ase Wa ba de, ti omi ba se yo ni oju aro, nigba naa ni ki o ko sinu oko oju-omi gbogbo nnkan ni orisi meji tako-tabo ati ara ile re, ayafi eni ti oro naa ko le lori ninu won (fun iparun). Ma se ba Mi soro nipa awon t’o sabosi; dajudaju A oo te won ri sinu omi ni

[28] Nigba ti o ba jokoo sinu oko oju-omi naa, iwo ati awon t’o wa pelu re, so pe: 'Ope ni fun Allahu, Eni ti O gba wa la lowo ijo alabosi

[29] So pe: “Oluwa mi, so mi kale si ibuso ibukun. Iwo si loore julo ninu awon amunigunle.”

[30] Dajudaju awon ami wa ninu iyen. Awa si ni A n dan eda wo

[31] Leyin naa, A mu awon iran miiran wa leyin won

[32] A tun ran Ojise kan si won laaarin ara won (lati jise) pe: “E josin fun Allahu. E o ni olohun miiran leyin Re. Nitori naa, se e o nii beru (Re) ni?”

[33] Awon olori t’o sai gbagbo ninu ijo re, awon t’o pe ipade Ojo Ikeyin niro, awon ti A se gbedemuke fun ninu isemi aye yii, won wi pe: "Ki ni eyi bi ko se abara kan bi iru yin; o n je ninu ohun ti e n je, o si n mu ninu ohun ti e n mu

[34] Ti e ba fi le tele abara kan bi iru yin, dajudaju e ma ti di eni ofo niyen

[35] Se o n se adehun fun yin pe nigba ti e ba ku, ti e si di erupe ati egungun tan, dajudaju Won yoo mu yin jade (ni alaaye)

[36] Ohun ti Won n se ni adehun fun yin (yii) jinna tefetefe (si ododo)

[37] Ko si isemi aye kan mo ayafi eyi ti a n lo yii; awa kan n ku, awa kan n waye. Ko si si pe Won yoo gbe wa dide mo

[38] (Ojise naa) ko je kini kan bi ko se okunrin kan ti o da adapa iro mo Allahu. Awa ko si nii gba a gbo

[39] (Ojise naa) so pe: "Oluwa mi, saranse fun mi nitori pe won pe mi ni opuro

[40] (Allahu) so pe: “Laipe nse ni won yoo di alabaamo.”

[41] Nitori naa, ohun igbe mu won lona eto. A si so won di panti. Nitori naa, ki ijinna si ike wa fun ijo alabosi

[42] Leyin naa, A tun mu awon iran miiran wa leyin won

[43] Ijo kan ko nii lo siwaju akoko (iparun) re, won ko si nii sun (iparun won) siwaju

[44] Leyin naa, A ran awon Ojise Wa nise ni telentele. Igbakigba ti Ojise ijo kan ba de, won n pe e ni opuro. A si mu apa kan won tele apa kan ninu iparun. A tun so won di itan. Nitori naa, ki ijinna si ike wa fun ijo ti ko gbagbo lododo

[45] Leyin naa, A ran (Anabi) Musa ati omo-iya re (Anabi) Harun nise pelu awon ami Wa ati eri ponnbele

[46] (A ran won nise) si Fir‘aon ati awon ijoye re. Sugbon won segberaga, won si je ijo olujegaba

[47] Won wi pe: “Se ki a gba abara meji bi iru wa gbo, nigba ti o je pe eru wa ni awon eniyan won?”

[48] Nitori naa, won pe awon mejeeji ni opuro. Won si wa ninu awon eni- iparun

[49] Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira nitori ki won le mona

[50] A se omo Moryam ati iya re ni ami kan. A si se ibugbe fun awon mejeeji si ibi giga kan, t’o ni ibugbe, t’o si ni omi iseleru

[51] Eyin Ojise, e je ninu awon nnkan daadaa, ki e si se ise rere. Dajudaju Emi ni Onimo nipa ohun ti e n se nise

[52] Ati pe dajudaju (’Islam) yii ni esin yin. (O je) esin kan soso. Emi si ni Oluwa yin. Nitori naa, e beru Mi

[53] Sugbon won ge oro esin won laaarin ara won si kelekele. Ijo kookan si n yo si ohun t’o n be ni odo won

[54] Nitori naa, fi won sile sinu isina won titi di igba kan na

[55] Se won n lero pe (bi) A se n fi dukia ati omo nikan se iranlowo fun won

[56] ni A oo se maa yara ti awon oore si odo won lo (titi laelae). Rara, won ko fura ni

[57] Dajudaju awon t’o n paya (isiro-ise) fun ipaya won ninu Oluwa won

[58] ati awon t’o n gba awon ayah Oluwa won gbo

[59] ati awon ti ki i sebo si Oluwa won

[60] ati awon t’o n se ohun rere (ninu ise) ti won se, pelu iberu ninu okan won pe dajudaju awon yoo pada si odo Oluwa won

[61] awon wonyen ni won n yara se awon ise rere. Awon si ni asiwaju ninu (awon esan) ise naa

[62] Ati pe A ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. Tira kan t’o n so ododo (nipa ise eda) n be lodo Wa. A o si nii sabosi si won

[63] Amo okan awon alaigbagbo wa ninu ifonufora nipa (al-Ƙur’an) yii. Ati pe won ni awon ise kan lowo, ti o yato si ise rere yen. Won si n se ise naa

[64] titi di igba ti A maa gba awon onigbedemuke ninu won mu pelu iya. Nigba naa ni won maa ke gbajari

[65] E ma kee gbajari lonii. Dajudaju ko si eni ti o maa ran yin lowo lodo Wa

[66] Won kuku n ka awon ayah Mi fun yin. Amo nse ni e n fa seyin (nibi ododo)

[67] E si n fi Kaaba segberaga, e tun n fi oru yin so isokuso (nipa al-Ƙur’an)

[68] Se won ko ronu si oro naa ni? Tabi ohun t’o de ba won je ohun ti ko de ba awon baba won akoko ri ni

[69] Tabi won ko mo Ojise won mo ni won fi di alatako re

[70] Tabi won n wi pe alujannu kan n be lara re ni? Rara o. O mu ododo wa ba won ni. Amo opolopo won si je olukorira ododo

[71] Ti o ba je pe (Allahu), Oba Ododo tele ife-inu won ni, awon sanmo ati ile ati awon t’o wa ninu won iba kuku ti baje. Sugbon A mu isiti nipa oro ara won wa fun won ni, won si n gbunri kuro nibi isiti (ti A mu wa fun) won

[72] Tabi o n beere owo-oya kan lowo won ni? Owo-oya Oluwa re loore julo. Ati pe Oun l’oore julo ninu awon olupese

[73] Ati pe dajudaju o n pe won soju ona taara ni

[74] Awon ti ko si gba Ojo Ikeyin gbo ni won n seri kuro loju ona naa

[75] Ti o ba je pe A ke won (nile aye), ti A si gbe gbogbo isoro ara won kuro fun won, won iba tun wonkoko mo itayo enu-ala won, ti won yoo maa pa ridarida (ninu isina)

[76] Dajudaju A fi iya je won. Amo won ko teriba fun Oluwa won, won ko si rawo rase si I

[77] titi di igba ti A fi silekun iya lile fun won; nigba naa ni won soreti nu

[78] (Allahu), Oun ni Eni ti O se igboro, iriran ati okan fun yin, idupe yin si kere

[79] Oun ni Eni ti O da yin sori ile, odo Re si ni won yoo ko yin jo si

[80] Oun ni Eni t’O n so eda di alaaye, O n so eda di oku, tiRe si ni itelentele ati iyato oru ati osan, se e o nii se laakaye ni

[81] Rara (won ko nii se laakaye, sebi) iru ohun ti awon eni akoko wi ni awon naa wi

[82] Won wi pe: “Se nigba ti a ba ti ku, ti a ti di erupe ati egungun, se won yoo gbe wa dide ni

[83] Won kuku ti se adehun yii fun awa ati awon baba wa teletele. Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko.”

[84] So pe: “Ta ni Eni ti O ni ile ati eni ti o wa ni ori re ti e ba mo?”

[85] Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Se e o nii lo iranti ni?”

[86] So pe: “Ta ni Oluwa awon sanmo mejeeje ati Oluwa Ite nla?”

[87] Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Se e o nii beru (Re) ni?”

[88] So pe: “Ta ni Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re, (Eni ti) O n gba eda la ninu iya, (ti) ko si si eni ti o le gba eda la nibi iya Re ti e ba mo?” So pe: “Ta ni Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re, (Eni ti) O n gba eda la ninu iya, (ti) ko si si eni ti o le gba eda la nibi iya Re ti e ba mo?”

[89] Won a wi pe: “Ti Allahu ni.” So pe: “Nitori naa, bawo ni won se n dan yin?”

[90] Amo sa, ododo ni A mu wa ba won. Dajudaju awon si ni opuro

[91] Allahu ko fi eni kan kan se omo, ko si si olohun kan pelu Re. (Ti ko ba ri bee) nigba naa, olohun kookan iba ti ko eda t’o da lo, apa kan won iba si bori apa kan. Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re nipa omo bibi)

[92] (Allahu) Onimo-ikoko ati gbangba. Nitori naa, O ga tayo nnkan ti won fi n sebo si I

[93] So pe: “Oluwa mi, O see se ki O fi ohun ti won n se ni adehun fun won han mi

[94] Oluwa mi, ma se fi mi sinu ijo alabosi.”

[95] Dajudaju Awa lagbara lati fi ohun ti A se ni ileri fun won han o

[96] Fi eyi t’o dara ti aidara danu. Awa nimo julo nipa ohun ti won fi n royin (Wa)

[97] So pe: "Oluwa mi, mo n sadi O nibi royiroyi t’awon esu

[98] Mo n sadi O, Oluwa mi, nibi ki won wa ba mi

[99] (Won n semi lo) titi di igba ti iku fi maa de ba okan ninu won. O si maa wi pe: “Oluwa mi, E da mi pada (sile aye)

[100] nitori ki ng le se ise rere ninu eyi ti mo gbe ju sile. Ko ri bee rara, dajudaju o je oro kan ti o kan n wi ni, (amo) gaga ti wa ni eyin won titi di ojo ti A oo gbe won dide. ayeta okigbe

[101] Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde, ko nii si ibatan laaarin won ni ojo yen, won ko si nii bira won leere ibeere

[102] Enikeni ti osuwon (ise rere) re ba tewon, awon wonyen ni olujere

[103] Enikeni ti osuwon (ise rere) re ba fuye, awon wonyen ni awon t’o se emi ara won lofo. Olusegbere si ni won ninu ina Jahanamo

[104] Ina yoo maa jo won loju. Won yo si wa ninu re, ti Ina yoo ti ba won loju je

[105] Se won ki i ka awon ayah Mi fun yin ni, amo ti e n pe e niro

[106] Won wi pe: "Oluwa wa, ori buruku l’o kolu wa; awa si je ijo olusina

[107] Oluwa wa, mu wa jade kuro ninu Ina. Ti a ba fi le pada (sibi ise ibi nile aye), dajudaju nigba naa alabosi ni awa

[108] (Allahu) so pe: “E teri sinu re. E ma se ba Mi soro.”

[109] Dajudaju igun kan wa ninu awon erusin Mi, ti won n so pe: “Oluwa wa, a gbagbo ni ododo. Nitori naa, forijin wa, ki O si ke wa. Iwo si l’oore julo ninu awon alaaanu.”

[110] Sugbon e so won di oniyeye to bee ge ti awon yeye (yin) fi mu yin gbagbe iranti Mi. Eyin si n fi won rerin-in

[111] Dajudaju Mo san won ni esan ni oni nitori suuru won; dajudaju awon, awon ni olujere

[112] (Allahu) so pe: "Odun meloo ni eyin (alaigbagbo) lo lori ile aye

[113] Won wi pe: “A lo ojo kan tabi abala ojo kan, bi awon olusiro-ojo leere wo.”

[114] (Allahu) so pe: “E ko gbe ile aye bi ko se fun igba die, ti o ba je pe e mo.”

[115] Se e lero pe A kan seda yin fun iranu ni, ati pe dajudaju won o nii da yin pada sodo Wa?”

[116] Nitori naa, Allahu Oba Ododo ga. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun, Oluwa Ite alapon-onle

[117] Eni ti o ba pe olohun miiran pelu Allahu, ko ni eri lowo lori re. Dajudaju isiro-ise re si wa lodo Oluwa re. Dajudaju awon alaigbagbo ko nii jere

[118] So pe: “Oluwa mi, saforijin, ki O si ke (mi). Iwo si l’oore julo ninu awon alaaanu.”

Ìmọ́lẹ̀

Surah 24

[1] (Eyi ni) Surah kan ti A sokale. A se e ni ofin. A si so awon ayah t’o yanju kale sinu re nitori ki e le lo iranti

[2] Onisina lobinrin ati onisina lokunrin, e na enikookan ninu awon mejeeji ni ogorun-un koboko. E ma se je ki aanu won se yin nipa idajo Allahu ti e ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Ki igun kan ninu awon onigbagbo ododo si jerii si iya awon mejeeji. ti o ba di oyun ti oko re ko si mo won ko nii fun won letoo si oorun ife miiran mo tori pe ko si itakoko yigi laaarin won. Bi o tile je pe a ri ninu awon onimo esin t’o ni won le se itakoko yigi obinrin naa fun arakunrin t’o se zina pelu re lori oyun zina naa nitori ki won le maa je igbadun ara won lo ni ona eto eyi ti o dara julo ni pe

[3] Onisina lokunrin ko nii se sina pelu eni kan bi ko se onisina lobinrin (egbe re) tabi osebo lobinrin. Onisina lobinrin, eni kan ko nii ba a se sina bi ko se onisina lokunrin (egbe re) tabi osebo lokunrin. A si se iyen ni eewo fun awon onigbagbo ododo

[4] Awon t’o n fi esun sina kan awon omoluabi lobinrin, leyin naa ti won ko mu awon elerii merin wa, e na won ni ogorin koboko. E ma se gba eri won mo laelae; awon wonyen si ni obileje

[5] Ayafi awon t’o ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[6] Awon t’o n fi esun sina kan awon iyawo won, ti ko si si elerii fun won afi awon funra won, eri eni kookan won ni ki o fi Allahu jerii ni ee merin pe dajudaju oun wa ninu awon olododo

[7] Ee karun-un si ni pe ki ibi dandan Allahu maa ba oun, ti oun ba wa ninu awon opuro

[8] Ohun ti o maa ye iya fun iyawo ni pe ki o fi Allahu jerii ni ee merin pe dajudaju oko oun wa ninu awon opuro

[9] Ee karun-un si ni pe ki ibinu Allahu maa ba oun, ti oko oun ba wa ninu awon olododo

[10] Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni (Allahu iba maa tu asiri yin ni). Dajudaju Allahu ni Olugba-ironupiwada, Ologbon

[11] Dajudaju awon t’o mu adapa iro wa je ijo kan ninu yin. E ma se lero pe aburu ni fun yin. Rara o, oore ni fun yin. Eni kookan ninu won ti ni ohun ti o da ni ese. Ati pe eni ti o da (ese) julo ninu won, iya nla ni tire

[12] Nigba ti e gbo o, ki ni ko je ki awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin ro daadaa rora won, ki won si so pe: “Eyi ni adapa iro ponnbele.”

[13] Ki ni ko je ki won mu elerii merin wa lori re? Nitori naa, nigba ti won ko ti mu awon elerii wa, awon wonyen, awon ni opuro lodo Allahu

[14] Ti ki i ba se ti oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni ile aye ati ni orun ni, dajudaju iya nla iba fowo ba yin nipa ohun ti e n so kiri ni isokuso

[15] (E ranti) nigba ti e n gba a (laaarin ara yin) pelu ahon yin, ti e si n fi enu yin so ohun ti e o nimo nipa re; e lero pe nnkan t’o fuye ni, nnkan nla si ni lodo Allahu

[16] Nigba ti e gbo o, ki ni ko je ki e so pe: “Ki i se eto fun wa pe ki a so eyi. Mimo ni fun O (Allahu)! Eyi ni iparo-moni t’o tobi.”

[17] Allahu n se waasi fun yin pe ki e ma se pada sibi iru re mo laelae ti e ba je onigbagbo ododo

[18] Allahu n salaye awon ayah naa. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[19] Dajudaju awon t’o nifee si ki (oro) ibaje maa tan kale nipa awon t’o gbagbo ni ododo, iya eleta-elero n be fun won ni aye ati ni orun. Allahu nimo, eyin ko si nimo

[20] Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni (Allahu iba tete fiya je yin ni). Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun

[21] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se tele awon oju-ese Esu. Enikeni ti o ba si tele awon oju-ese Esu, dajudaju (Esu) yoo pase iwa ibaje ati aburu (fun un). Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni, eni kan iba ti mo ninu yin laelae. Sugbon Allahu n safomo eni ti O ba fe. Allahu si ni Olugbo, Onimo

[22] Ki awon t’o ni ola ati igbalaaye ninu yin ma se bura pe awon ko nii se daadaa si awon ibatan, awon mekunnu ati awon t’o gbe ilu won ju sile nitori esin Allahu. Ki won saforijin, ki won si samojukuro. Se e o fe ki Allahu forijin yin ni? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[23] Dajudaju awon t’o n paro sina mo awon omoluabi l’obinrin, awon ti sina ko si lori okan won, awon onigbagbo ododo lobinrin, A ti sebi le won ni aye ati ni orun. Iya nla si wa fun won

[24] Ni ojo ti awon ahon won, owo won ati ese won yoo maa jerii tako won nipa ohun ti won n se nise

[25] ni ojo yen ni Allahu yoo san won ni esan won ti o to si won. Won yo si mo pe dajudaju Allahu, Oun ni Ododo ponnbele

[26] Awon obinrin buruku wa fun awon okunrin buruku. Awon okunrin buruku si wa fun awon obinrin buruku. Awon obinrin rere wa fun awon okunrin rere. Awon okunrin rere si wa fun awon obinrin rere. Awon (eni rere) wonyi mowo-mose ninu (aidaa) ti won n so si won. Aforijin ati ese alapon-onle n be fun won

[27] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se wo awon ile kan yato si awon ile yin titi e maa fi toro iyonda ati (titi) e maa fi salamo si awon ara inu ile naa. Iyen loore julo fun yin nitori ki e le lo iranti

[28] Ti e o ba si ba eni kan kan ninu ile naa, e ma se wo inu re titi won yoo fi yonda fun yin. Ti won ba si so fun yin pe ki e pada, nitori naa e pada. Ohun l’o fo yin mo julo. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti e n se nise

[29] Ko si ese fun yin lati wo inu awon ile kan ti ki i se ibugbe, ti anfaani wa ninu re fun yin . Allahu mo ohun ti e n safi han re ati ohun ti e n fi pamo

[30] So fun awon onigbagbo ododo lokunrin pe ki won re oju won nile, ki won si so abe won. Iyen fo won mo julo. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti won n se nise

[31] So fun awon onigbagbo ododo lobinrin pe ki won re oju won nile, ki won si so abe won. Ki won ma safi han oso won afi eyi ti o ba han ninu re.1 Ki won fi ibori won bo igba-aya won.2 Ati pe ki won ma safi han oso won afi fun awon oko won tabi awon baba won tabi awon baba oko won tabi awon omokunrin won tabi awon omokunrin oko won tabi awon arakunrin won tabi awon omokunrin arakunrin won tabi awon omokunrin arabinrin won tabi awon obinrin (egbe) won tabi awon erukunrin won tabi awon t’o n tele obinrin fun ise riran, ti won je okunrin akura tabi awon omode ti ko ti i da ihoho awon obinrin mo (si nnkan kan). Ki won ma se fi ese won rin irin-kokoka nitori ki awon (eniyan) le mo ohun ti won fi pamo (sara) ninu oso won. Ki gbogbo yin si ronu piwada sodo Allahu, eyin onigbagbo ododo nitori ki e le jere

[32] E fi iyawo fun awon apon ninu yin ati awon eni ire ninu awon erukunrin yin. (Ki e si wa oko rere fun) awon erubinrin yin. Ti won ba je alaini, Allahu yoo ro won loro ninu ola Re. Allahu si ni Olugbaaye, Onimo

[33] Ki awon ti ko ri (owo lati fe) iyawo mu oju won kuro nibi isekuse titi Allahu yoo fi ro won loro ninu ola Re.1 Awon t’o n wa iwe ominira ninu awon eru yin, e ko iwe ominira fun won ti e ba mo ohun rere nipa won. Ki e si fun won ninu dukia Allahu ti O fun yin. (Nitori dukia aye ti e n wa), e ma se je awon erubinrin yin nipa lati lo se sina, ti won ba fe so abe won nibi isekuse.2 Enikeni ti o ba je won nipa, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun leyin ti e ti je won nipa

[34] Dajudaju A ti so awon ami t’o yanju, itan awon t’o ti lo siwaju yin ati waasi fun awon oluberu (Allahu) kale fun yin

[35] Allahu ni Olutan-imole sinu awon sanmo ati ile. Apejuwe imole Re da bi opo atupa kan ti atupa wa ninu re. Atupa naa si wa ninu dingi. Dingi naa da bi irawo kan t’o n tan yanranyanran. Won n tan (imole naa) lati ara igi ibukun kan, igi zaetun. Ki i gba imole nigba ti oorun ba n yo jade tabi nigba ti oorun ba n wo. Epo (imole) re fee da mu imole wa, ina ibaa ma de ibe. Imole lori imole ni. Allahu n to enikeni ti O ba fe si (ona) imole Re. Allahu n fi awon akawe lele fun awon eniyan. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[36] (Awon atupa ibukun naa wa) ninu awon ile kan (iyen awon mosalasi) eyi ti Allahu yonda pe ki won gbega,1 ki won si maa daruko Re ninu re. (Awon eniyan) yo si maa safomo fun Un ninu re ni aaro ati asale

[37] Awon okunrin ti owo ati kara-kata ko di lowo nibi iranti Allahu, irun kiki ati Zakah yiyo, awon t’o n paya ojo kan ti awon okan ati oju yoo maa yi si otun yi si osi

[38] (Won se rere wonyi) nitori ki Allahu le fi eyi t’o dara ninu ohun ti won se nise san won ni esan rere ati nitori ki O le se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Ati pe Allahu n pese arisiki fun eni ti O ba fe lai la isiro lo

[39] Awon t’o sai gbagbo, awon ise won da bi ahunpeena t’o wa ni papa, ti eni ti ongbe n gbe si lero pe omi ni titi di igba ti o de sibe, ko si ba kini kan nibe. O si ba Allahu nibi (ise) re (ni orun). (Allahu) si se asepe isiro-ise re fun un. Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise

[40] Tabi (ise awon alaigbagbo) da bi awon okunkun kan ninu ibudo jijin, ti igbi omi n bo o mole, ti igbi omi miiran tun wa ni oke re, ti esujo si wa ni oke re; awon okunkun biribiri ti apa kan won wa lori apa kan (niyi). Nigba ti o ba nawo ara re jade, ko ni fee ri i. Enikeni ti Allahu ko ba fun ni imole, ko le si imole kan fun un

[41] Se o o ri i pe dajudaju Allahu ni gbogbo eni t’o n be ninu awon sanmo ati lori ile n se afomo fun? Awon eye naa (n se bee) nigba ti won ba n na iye apa won? Ikookan won kuku ti mo bi o se maa kirun re ati bi o se maa se afomo re (fun Un). Allahu si ni Onimo nipa ohun ti won n se nise

[42] Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni abo eda

[43] Se o o ri i pe dajudaju Allahu n da esujo kaakiri ni? Leyin naa O n ko o jo mora won. Leyin naa, O n gbe won gun ara won, nigba naa ni o maa ri ojo ti o maa jade lati aarin re. Lati inu sanmo, O si n so awon yiyin kan (t’o da bi) awon apata kale si ori ile aye. O n mu un kolu eni ti O ba fe. O si n seri re kuro fun eni ti O ba fe. Kiko yanranyanran monamona inu esujo si fee le fo awon oju

[44] Allahu n mu oru ati osan tele ara won ni telentele. Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun awon t’o ni oju iriran

[45] Allahu seda gbogbo abemi lati inu omi. O wa ninu won, eyi t’o n fi aya re wo. O wa ninu won, eyi t’o n fi ese meji rin. O si wa ninu won, eyi t’o n fi merin rin. Allahu n seda ohun ti O ba fe. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[46] Dajudaju A ti so awon ayah t’o n yanju oro kale. Allahu si n to enikeni ti O ba fe si ona taara (’Islam)

[47] Won n wi pe: “A gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. A si tele (ase Won).” Leyin naa, igun kan ninu won n peyin da leyin iyen. Awon wonyen ki i se onigbagbo ododo

[48] Ati pe nigba ti won ba pe won si ti Allahu ati ti Ojise Re nitori ki o le sedajo laaarin won, nigba naa ni igun kan ninu won yoo maa gbunri

[49] Ti o ba si je pe awon ni won ni eto (are) ni, won yoo wa ba o ni tokan-tara

[50] Se arun wa ninu okan won ni tabi won seyemeji? Tabi won n paya pe Allahu ati Ojise Re yoo fi ejo won segbe ni? Rara o. Awon wonyen, awon ni alabosi

[51] Ohun ti o maa je oro awon onigbagbo ododo nigba ti won ba pe won si ti Allahu ati ti Ojise Re nitori ki o le sedajo laaarin won, ni pe won a so pe: “A gbo (ase), a si tele (ase).” Awon wonyen, awon ni olujere

[52] Enikeni ti o ba tele ti Allahu ati ti Ojise Re, ti o n paya Allahu, ti o si n beru Re, awon wonyen, awon ni olujere

[53] Won si fi Allahu bura ti ibura won si ni agbara pe: "Dajudaju ti o ba pase fun awon, dajudaju awon yoo jade." So pe: “E ma se bura mo. Titele ase (pelu ibura iro enu yin) ti di ohun mimo (fun wa).” Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[54] So pe: "E tele ti Allahu. Ki e si tele ti Ojise naa. Ti won ba peyin da, ohun ti A gbe ka a lorun l’o n be lorun re, ohun ti A si gbe ka yin lorun l’o n be lorun yin. Ti e ba si tele e, e maa mona taara. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele

[55] Allahu sadehun fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si se awon ise rere pe dajudaju O maa fi won se arole lori ile gege bi O se fi awon t’o siwaju won se arole. Dajudaju O maa fi aye gba esin won fun won, eyi ti O yonu si fun won. Leyin iberu won, dajudaju O maa fi ifayabale dipo re fun won. Won n josin fun Mi, won ko si fi nnkan kan sebo si Mi. Enikeni ti o ba si sai moore leyin iyen, awon wonyen, awon ni obileje

[56] E kirun. E yo Zakah. E tele Ojise naa nitori ki A le ke yin

[57] Ma se lero pe awon t’o sai gbagbo mori bo ninu iya lori ile. Ina ni ibugbe won. Ikangun naa si buru

[58] Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki awon eru yin ati awon ti ko ti i balaga ninu yin maa gba iyonda lodo yin nigba meta (wonyi): siwaju irun Subh, nigba ti e ba n bo aso yin sile fun oorun osan ati leyin irun ale. (Igba) meta fun iborasile yin (niyi). Ko si ese fun eyin ati awon leyin (asiko) naa pe ki won wole to yin; ki apa kan yin wole to apa kan. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah naa fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[59] Nigba ti awon omode yin ba si balaga, ki awon naa maa gba iyonda gege bi awon t’o siwaju won se gba iyonda. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah Re fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[60] Awon t’o ti dagba koja omo bibi ninu awon obinrin, awon ti ko reti ibalopo oorun ife mo, ko si ese fun won lati bo awon aso jilbab won sile, ti won ko si nii se afihan oso kan sita. Ki won si maa wo aso jilbab won lo bee loore julo fun won. Allahu si ni Olugbo, Onimo

[61] Ko si ese fun afoju, ko si ese fun aro, ko si ese fun alaisan, ko si si ese fun eyin naa lati jeun ninu ile yin, tabi ile awon baba yin, tabi ile awon iya yin, tabi ile awon arakunrin yin, tabi ile awon arabinrin yin, tabi ile awon arakunrin baba yin, tabi ile awon arabinrin baba yin, tabi ile awon arakunrin iya yin, tabi ile awon arabinrin iya yin, tabi (ile) ti e ni ikapa lori kokoro re, tabi (ile) ore yin. Ko si ese fun yin lati jeun papo tabi ni otooto. Nitori naa, ti e ba wo awon inu ile kan, e salamo sira yin. (Eyi je) ikini ibukun t’o dara lati odo Allahu. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah naa fun yin nitori ki e le se laakaye

[62] Awon onigbagbo ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Nigba ti won ba si wa pelu re lori oro kan ti o kan gbogbogbo, won ko nii lo titi won yoo fi gba iyonda lodo re. Dajudaju awon t’o n gba iyonda lodo re, awon wonyen ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Nitori naa, ti won ba gba iyonda lodo re fun apa kan oro ara won, fun eni ti o ba fe ni iyonda ninu won, ki o si ba won toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[63] E ma se ladisokan pe ipe Ojise laaarin yin da bi ipe apa kan fun apa kan. Allahu kuku ti mo awon t’o n yo sa lo ninu yin. Nitori naa, ki awon t’o n yapa ase re sora nitori ki idaamu ma baa de ba won, tabi nitori ki iya eleta-elero ma baa je won

[64] Gbo! Dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. O si ti mo ohun ti e wa lori re. (Ranti) ojo ti won yo da won pada si odo Re, O si maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

Òṣùwọ̀n

Surah 25

[1] Ibukun ni fun Eni ti O so oro-ipinya (ohun t’o n sepinya laaarin ododo ati iro) kale fun erusin Re nitori ki o le je olukilo fun gbogbo eda

[2] (Oun ni) Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile. Ko mu eni kan kan ni omo. Ko si akegbe fun Un ninu ijoba (Re). O da gbogbo nnkan. O si yan odiwon (irisi, isemi ati ayanmo) fun un niwon-niwon

[3] (Awon alaigbagbo) so awon kan di olohun leyin Allahu. Won ko si le da kini kan. A si da won ni. Won ko si ni ikapa inira tabi anfaani kan fun emi ara won. Ati pe won ko ni ikapa lori iku, isemi ati ajinde

[4] Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Ki ni eyi bi ko se adapa iro kan ti o da adapa re (mo Allahu), ti awon eniyan miiran si ran an lowo lori re.” Dajudaju (awon alaigbagbo) ti gbe abosi ati iro de

[5] Won tun wi pe: “Akosile alo awon eni akoko, ti o sadako re ni. Ohun ni won n pe fun un ni owuro ati ni asale.”

[6] So pe: "Eni ti O mo ikoko ti n be ninu awon sanmo ati ile l’O so o kale. Dajudaju Oun ni O n je Alaforijin, Asake-orun

[7] Won tun wi pe: “Ki lo mu Ojise yii, t’o n jeun, t’o n rin ninu awon oja? Nitori ki ni Won ko se so molaika kan kale fun un ki o le je olukilo pelu re

[8] Tabi (nitori ki ni) won ko se ju apoti-oro kan sodo re, tabi ki o ni ogba oko kan ti o ma maa je ninu re?” Awon alabosi si tun wi pe: “Ta ni e n tele bi ko se okunrin eleedi kan.”

[9] Wo bi won se fun o ni awon afiwe (buruku)! Nitori naa, won ti sina; won ko si le mona

[10] Ibukun ni fun Eni ti (o je pe) bi O ba fe, O maa soore t’o dara ju iyen fun o. (O si maa je) awon ogba ti awon odo yoo maa san ni isale re. O si maa fun o ni awon aafin kan

[11] Nse ni won pe Akoko naa niro. A si ti pese Ina t’o n jo sile de enikeni ti o ba pe Akoko naa niro

[12] Nigba ti (Ina naa) ba ri won lati aye kan ti o jinna, won yo si maa gbo ohun ibinu ati kikun (re)

[13] Nigba ti Won ba si ju won si aye t’o ha gadigadi ninu (Ina), ti won de owo won mo won lorun, won yo si maa kigbe iparun nibe

[14] (A o so pe): “E ma se kigbe iparun eyo kan, e kigbe iparun lopolopo.”

[15] So pe: “Nje iyen lo loore julo ni tabi Ogba Idera gbere, eyi ti A se ni adehun fun awon oluberu Allahu. O si je esan ati ikangun rere fun won

[16] Ohunkohun ti won ba n fe wa fun won ninu re. Olusegbere ni won (ninu re). (Eyi) je adehun ti won ti toro lodo Oluwa re

[17] Ati pe (ranti) ojo ti (Allahu) yoo ko awon aborisa ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu jo, (Allahu) yo si so pe: “Se eyin l’e si awon erusin Mi wonyi lona ni tabi awon ni won sina (funra won)?”

[18] Won wi pe: “Mimo ni fun O! Ko to fun wa lati mu awon kan ni alatileyin leyin Re. Sugbon Iwo l’O fun awon ati awon baba won ni igbadun, titi won fi gbagbe Iranti. Won si je eni iparun.”

[19] (Allahu so pe): “Dajudaju awon orisa ti pe eyin aborisa ni opuro nipa ohun ti e n so (pe olusipe ni won). Ni bayii won ko le gbe iya Ina kuro fun yin, won ko si le ran yin lowo. Enikeni ti o se abosi (ebo sise) ninu yin, A si maa fun un ni iya t’o tobi to wo.”

[20] A ko ran awon Ojise nise ri siwaju re afi ki won jeun, ki won si rin ninu oja. A ti fi apa kan yin se adanwo fun apa kan, nje e maa se suuru bi? Oluwa Re si n je Oluriran

[21] Awon ti ko reti ipade Wa (ni orun) wi pe: “Won ko se so awon molaika kale fun wa, tabi ki a ri Oluwa wa (soju nile aye)? Dajudaju won ti segberaga ninu emi won. Won si ti tayo enu-ana ni itayo-enu ala t’o tobi

[22] (Ranti) ojo ti won yoo ri awon molaika, ko nii si iro idunnu fun awon elese ni ojo yen. (Awon molaika) yo si so pe: “Eewo, eewo (ni iro idunnu fun eyin elese).”

[23] Ati pe A maa wa sibi ohun ti won se nise, A si maa so o di eruku afedanu

[24] Awon ero inu Ogba Idera, ni ojo yen, (ogba won) maa loore julo ni ibugbe. O si maa dara julo ni ibusinmi

[25] Ati pe (ranti) ojo ti sanmo yo faya pelu awon esujo funfun. A si maa so awon molaika kale taara

[26] Ijoba ododo ti ojo yen n je ti Ajoke-aye. O si je ojo kan ti o maa nira fun awon alaigbagbo

[27] (Ranti) ojo ti alabosi yoo je ika owo re mejeeji, o si maa wi pe: "Yee! Emi iba ti to ona kan (naa) pelu Ojise naa

[28] Egbe mi o, yee! Emi iba ti mu lagbaja ni ore ayo

[29] Dajudaju o ti si mi lona kuro nibi Iranti leyin ti o de ba mi. Dajudaju Esu n je adani-dasoro fun omoniyan

[30] Ojise naa so pe: “Oluwa mi dajudaju awon eniyan mi ti pa al-Ƙur’an yii ti.”

[31] Bayen ni A se awon kan ninu awon elese ni ota fun Anabi kookan. Oluwa re si to ni Afinimona ati Alaranse

[32] Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Won ko se so al-Ƙur’an kale fun un ni apapo ni ee kan naa?” (A so o kale diedie) bayen nitori ki A le fi rinle sinu okan re. A si ke e fun o diedie

[33] Won ko nii mu apeere kan wa fun o (bi ibeere lati fi tako o) afi ki A mu ododo (iyen, al-ƙur’an) ati alaye t’o dara julo wa fun o (lori re)

[34] Awon ti A maa ko jo lo sinu ina Jahanamo ni idojubole, awon wonyen ni aye won buru julo. Won si sina julo

[35] Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira. A tun se arakunrin re, Harun, ni amugbalegbee fun un

[36] A si so pe: “Eyin mejeeji, e lo sodo ijo t’o pe awon ayah Wa niro. A si pa ijo naa run patapata

[37] (Ranti) ijo (Anabi) Nuh. Nigba ti won pe awon Ojise ni opuro, A te won ri sinu omi. A si se won ni ami kan fun awon eniyan. A si ti pese iya eleta-elero sile de awon alabosi

[38] (Ranti) awon ijo ‘Ad, ijo Thamud, ijo Rass ati awon opolopo iran miiran (t’o n be) laaarin won

[39] Ikookan won ni A fun ni awon apejuwe (nipa awon t’o tako ododo). Ikookan won si ni A parun patapata

[40] Ati pe dajudaju won koja ni ilu ti A ro ojo buruku le lori. Se won ki i ri i ni? Rara, nse ni won ko reti Ajinde

[41] Nigba ti won ba si ri o, ko si ohun ti won yoo fi o se bi ko se yeye. (Won a wi pe): “Se eyi ni eni ti Allahu gbe dide ni Ojise

[42] O ma fee seri wa kuro nibi awon olohun wa, ti ki i ba se pe a taku sori re.” Laipe won maa mo eni ti o sina julo nigba ti won ba ri iya

[43] So fun mi nipa eni ti o so ife-inu re di olohun re! Nitori naa, se iwo maa je alaabo fun un ni (nibi iya)

[44] Tabi iwo n ro pe dajudaju opolopo won n gboran tabi pe won n se laakaye? Ki ni won na, bi ko se bi agutan. Won wule sina julo

[45] Se o o ri (ise) Oluwa re ni, bi O se fe okunkun owuro loju (soju sanmo)? Ti O ba fe ni, iba da a duro sibe. Leyin naa, A fi oorun se atoka si bibe okunkun

[46] Leyin naa, A (fi imole oorun) mu okunkun (kuro nita) wa si odo Wa ni mimu diedie (ki ojumo le mo)

[47] Ati pe Oun ni Eni ti O se oru ni ibora fun yin. (O se) oorun ni isinmi (fun yin). O tun se osan ni asiko itusita (fun wiwa ije-imu)

[48] Oun si ni Eni t’’O n ran ategun ni iro-idunnu siwaju ike Re. A si so omi mimo kale lati sanmo

[49] nitori ki A le fi so oku ile di aye ile ati nitori ki A le fun eran-osin ati opolopo eniyan ninu awon ti A da ni omi mu

[50] Dajudaju A ti pin omi yii laaarin won nitori ki won le ranti (ike Oluwa won). Sugbon opolopo eniyan ko (lati ranti) afi aimoore

[51] Ti o ba je pe A ba fe ni, A iba gbe olukilo kan dide ninu ilu kookan

[52] Nitori naa, ma se tele awon alaigbagbo. Ki o si fi (al-Ƙur’an) ja won ni ogun t’o tobi

[53] Oun ni Eni ti O mu awon odo meji san kiri. Eyi (ni omi) t’o dun gan-an. Eyi si (ni omi) iyo t’o moro. O fi gaga si aarin awon mejeeji. (O si) se e ni eewo ponnbele (fun won lati ko inira ba eda)

[54] Oun ni Eni ti O seda abara lati inu omi. O se ibatan ebi ati ibatan ana fun un, Oluwa re si n je Alagbara

[55] Won n josin fun leyin Allahu ohun ti ko le se won ni anfaani, ti ko si le ko inira ba won. Alaigbagbo je oluranlowo (fun Esu) lati tako Oluwa re

[56] A ko si ran o nise tayo ki o je oniroo-idunnu ati olukilo

[57] So pe: “Emi ko beere owo-oya kan lowo yin lori re afi eni ti o ba fe mu ona (daadaa) to lo si odo Oluwa re.”

[58] Gbarale Alaaye ti ko nii ku. Se afomo pelu idupe fun Un. Allahu si to ni Alamotan nipa ese awon erusin Re

[59] (Oun ni) Eni ti O seda awon sanmo, ile ati awon nnkan t’o n be laaarin mejeeji laaarin ojo mefa. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. Ajoke-aye ni, nitori naa, beere nipa Re (lodo Re nitori pe, O je) Alamotan

[60] Nigba ti won ba so fun won pe: “E fori kanle fun Ajoke-aye.” Won a wi pe: “Ki ni Ajoke-aye? Se ki a fori kanle fun ohun ti o n pa wa lase re ni?” (Ipepe naa) si mu won lekun ni sisa-seyin

[61] Ibukun ni fun Eni ti O se awon irawo sinu sanmo. O tun se oorun ati osupa ni imole sinu re

[62] Oun ni Eni ti O se oru ati osan ni itelentele (ti ikini yato si ikeji) nitori eni ti o ba gbero lati se iranti (Allahu) tabi ti o ba gbero idupe (fun Un)

[63] Awon erusin Ajoke-aye ni awon t’o n rin jeeje lori ile. Nigba ti awon ope ba si doju oro ko won, won yoo so oro alaafia

[64] (Awon ni) awon t’o n lo oru won ni iforikanle ati iduro-kirun fun Oluwa won

[65] (Awon ni) awon t’o n so pe: “Oluwa wa, gbe iya ina Jahanamo kuro fun wa. Dajudaju iya re je iya ainipekun

[66] Dajudaju o buru ni ibugbe ati ibuduro

[67] Awon ti o je pe nigba ti won ba nawo, won ko na ina-apa, won ko si sahun; (inawo won) wa laaarin iyen ni iwontun-wonsi

[68] (Awon ni) awon ti ko pe olohun miiran mo Allahu. Won ko pa emi ti Allahu se (pipa re) ni eewo afi ni ona eto. Ati pe won ko se zina. Enikeni ti o ba se (aburu) yen, o maa pade (iya) ese

[69] A oo se iya ni ilopo fun un ni Ojo Ajinde. O si maa se gbere ninu re ni eni yepere

[70] Afi eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni Allahu yoo fi ise rere ropo ise aburu won (iyen, nipa ironupiwada won). Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

[71] Enikeni ti o ba ronu piwada, ti o si se ise rere, (ki o mo) pe dajudaju o n ronu piwada patapata sodo Allahu ni

[72] (Awon ni) awon ti ko jerii eke. Ti won ba si koja nibi ibaje, won a koja pelu aponle

[73] (Awon ni) awon ti o je pe ti won ba fi awon ayah Oluwa won seranti fun won, won ko da lule bi aditi ati afoju

[74] (Awon ni) awon t’o n so pe: “Oluwa wa, ta wa ni ore itutu-oju lati ara awon iyawo wa ati awon omo wa. Ki O si se wa ni asiwaju fun awon oluberu (Re).”

[75] Awon wonyen, ipo giga (ninu Ogba Idera) ni A maa fi san won ni esan nitori pe won se suuru. Ikini ati sisalamo ni A oo fi maa pade won ninu re

[76] Olusegbere ni won ninu re. O dara ni ibugbe ati ibuduro

[77] So pe: "Oluwa mi ko ka yin kun ti ki i ba se adua yin. E kuku ti pe (awon ayah Re) niro. Laipe o si maa di iya ainipekun (fun yin)

Àwọn Akéwì

Surah 26

[1] To sin mim

[2] Iwonyi ni awon ayah Tira t’o n yanju oro eda

[3] Nitori ki ni o se maa para re pe won ko je onigbagbo ododo

[4] Ti A ba fe, A maa so ami kan kale fun won lati sanmo. Awon orun won ko si nii ye teriba fun un

[5] Ko si iranti kan ti o maa de ba won ni titun lati odo Ajoke-aye afi ki won je olugbunri kuro nibe

[6] Dajudaju won ti pe (ayah Wa) niro. Nitori naa, awon iro ohun ti won n fi se yeye n bo wa ba won

[7] Se won ko ri ile pe meloo meloo ninu gbogbo orisirisi nnkan alapon-onle ti A mu hu jade lati inu re

[8] Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo

[9] Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

[10] (Ranti) nigba ti Oluwa re pe (Anabi) Musa pe: "Lo ba ijo alabosi

[11] ijo Fir‘aon (ki o si so fun won) pe 'Se won ko nii beru (Allahu) ni

[12] O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro

[13] O si maa je inira fun mi (ti won ba pe mi ni opuro). Ahon mi ko si ja gaaraga. Nitori naa, ranse si Harun

[14] Ati pe mo ni ese kan lorun lodo won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi

[15] (Allahu) so pe: "Rara (won ko le pa o). Nitori naa, ki eyin mejeeji mu awon ami (ise iyanu) Wa lo (ba won). Dajudaju Awa n be pelu yin; A n gbo (oro yin)

[16] Eyin mejeeji, e lo ba Fir‘aon. Ki e so fun un pe: 'Dajudaju awa ni Ojise Oluwa gbogbo eda

[17] (A n so fun o) pe ki o je ki awon omo ’Isro’il maa ba wa lo

[18] (Fir‘aon) wi pe: “Se ki i se ni aarin wa ni a ti to o ni kekere ni, ti o si gbe ni odo wa fun odun pupo ninu isemi aye re

[19] O si se ise owo re ti o se (si wa). Iwo si wa ninu awon alaimoore.”

[20] (Anabi Musa) so pe: "Mo se e nigba naa nigba ti mo wa ninu awon alaimokan ni

[21] Mo si sa fun yin nigba ti mo beru yin. Nitori naa, Allahu ti ta mi lore ipo Anabi. O si se mi ni (okan) ninu awon Ojise

[22] Ati pe iyen ni idera ti o n se iregun re le mi lori. Pe o so awon omo ’Isro’il di eru (nko)

[23] Fir‘aon wi pe: “Ki ni Oluwa gbogbo eda?”

[24] (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni)

[25] (Fir‘aon) wi fun awon t’o wa ni ayika re pe: “Se e e gbo oro (t’o n so ni)?”

[26] (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko.”

[27] (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju Ojise yin eyi ti won ran si yin, were ma ni.”

[28] (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa ibuyo oorun, ibuwo oorun ati ohunkohun t’o n be laaarin awon mejeeji, ti e ba maa n se laakaye.”

[29] (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju ti o ba fi le josin fun olohun kan yato si mi, dajudaju mo maa so o di ara awon elewon.”

[30] (Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe mo mu kini kan t’o yanju wa fun o nko?”

[31] (Fir‘aon) wi pe: “Mu un wa nigba naa ti iwo ba wa ninu awon olododo.”

[32] Nitori naa, o ju opa re sile, o si di ejo ponnbele

[33] O tun fa owo re yo sita, o si di funfun fun awon oluworan

[34] (Fir‘aon) wi fun awon ijoye ti won wa ni ayika re pe: “Dajudaju eyi ni onimo nipa idan pipa

[35] O fe ko yin kuro lori ile yin ni. Ki ni ohun ti e maa mu wa ni imoran?”

[36] Won wi pe: "Da oun ati arakunrin re duro na, ki o si ran awon akonijo si awon ilu

[37] (pe) ki gbogbo onimo nipa idan pipa wa ba o

[38] Won si ko awon opidan jo ni asiko ti won fi adehun si ni ojo ti (gbogbo ilu) ti mo

[39] Won si wi fun awon eniyan pe: "Se eyin maa ko jo (sibe) bi

[40] Nitori ki a le tele awon opidan ti o ba je pe awon ni olubori

[41] Nigba ti awon opidan de, won wi fun Fir‘aon pe: “Nje owo-oya kan wa fun wa, ti o ba je pe awa gan-an la je olubori?”

[42] (Fir‘aon) wi pe: “Bee ni, dajudaju nigba naa e maa wa ninu awon alasun-unmo (mi).”

[43] (Anabi) Musa so fun won pe: “E ju ohun ti e fe ju sile.”

[44] Won si ju awon okun won ati opa won sile. Won wi pe: “Pelu ogo Fir‘aon, dajudaju awa, awa ni olubori.”

[45] Nigba naa, (Anabi) Musa ju opa re sile. O si n gbe ohun ti won pa niro kale mi kalokalo

[46] Nitori naa, ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan wo lule, ti won fori kanle (fun Allahu)

[47] Won so pe: "A gbagbo ninu Oluwa gbogbo eda

[48] Oluwa (Anabi) Musa ati Harun

[49] Fir‘aon wi pe: “E gba A gbo siwaju ki ng to yonda fun yin! Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Laipe e n bo wa mo. Dajudaju mo maa ge owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Leyin naa, dajudaju mo maa kan gbogbo yin mogi.”

[50] (Awon opidan) so pe: “Ko si inira fun wa! Dajudaju awa yo si fabo si odo Oluwa wa

[51] Dajudaju awa n reti pe Oluwa wa yoo se aforijin awon asise wa fun wa nitori pe awa je eni akoko (ti o je) onigbagbo ododo.”

[52] A fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Mu awon erusin Mi rin ni oru (nitori pe) dajudaju won yoo lepa yin.”

[53] Fir‘aon si ran awon akonijo sinu awon ilu (lati so pe)

[54] Dajudaju awon (omo ’Isro’il) wonyi, ijo perete die ni won

[55] Ati pe dajudaju won ti se ohun t’o n bi wa ninu

[56] Dajudaju gbogbo wa ni ki a si wa tifura-tifura

[57] Nitori naa, A mu (ijo Fir‘aon) jade kuro ninu awon ogba oko ati iseleru omi

[58] ati awon apoti-oro ati ibujokoo aponle

[59] Bayen (loro ri). A si jogun re fun awon omo ’Isro’il

[60] Won si lepa won ni asiko ti oorun yo

[61] Nigba ti ijo mejeeji rira won, awon ijo (Anabi) Musa so pe: “Dajudaju won yoo le wa ba.”

[62] (Anabi) Musa so pe: “Rara, dajudaju Oluwa mi n be pelu mi. O si maa fi ona mo mi.”

[63] A si fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Fi opa re na agbami okun.” (O fi na a). O si pin (si ona mejila). Ipin kookan si da bi apata nla

[64] A si mu ijo keji (iyen, ijo Fir‘aon) sunmo ibe yen

[65] A gba (Anabi) Musa ati gbogbo awon t’o n be pelu re la patapata

[66] Leyin naa, A te ijo keji ri (sinu agbami)

[67] Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo

[68] Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

[69] Ka iroyin (Anabi) ’Ibrohim fun won

[70] Nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: “Ki ni nnkan ti e n josin fun na?”

[71] Won wi pe: “A n josin fun awon ere kan ni. A o si nii ye taku ti won lorun.”

[72] (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Nje won n gbo oro yin nigba ti e ba n pe won

[73] Tabi (se) won le se yin ni oore tabi won le fi inira kan yin?”

[74] Won wi pe: “Rara o! A ba awon baba wa, ti won n se bee ni”

[75] (Anabi ’Ibrohim) so pe: " E so fun mi, ki ni nnkan ti e n josin fun

[76] eyin ati awon baba yin isaaju

[77] Dajudaju awon ni ota fun mi ayafi Oluwa gbogbo eda

[78] (Oun ni) Eni ti O seda mi. Nitori naa, O maa fi ona mo mi

[79] Eni t’O n fun mi ni jije, t’O n fun mi ni mimu

[80] Ati pe nigba ti ara mi ko ba ya, Oun l’O n wo mi san

[81] Eni ti O maa pa mi, leyin naa, O maa so mi di alaaye

[82] Eni ti mo ni ireti si pe O maa fori awon asise mi jin mi ni Ojo Esan

[83] Oluwa mi, ta mi ni ore ipo Anabi. Da mi po mo awon eni rere

[84] Je ki awon t’o n bo leyin (mi) maa soro mi pelu daadaa

[85] Se mi ni okan ninu awon olujogun Ogba Idera

[86] Ki O si forijin baba mi. Dajudaju o je okan ninu awon olusina

[87] Ma se doju ti mi ni ojo ti won yoo gbe eda dide

[88] Ojo ti dukia kan tabi awon omo ko nii sanfaani

[89] Ayafi eni ti o ba de odo Allahu pelu okan mimo

[90] A maa mu Ogba Idera sunmo awon oluberu (Allahu)

[91] Won si maa fi ina Jehim han awon olusina

[92] won yo si so fun won pe: “Nibo ni nnkan ti e n josin fun wa?”

[93] (Nnkan ti e n josin fun) leyin Allahu, se won le ran yin lowo tabi se won le ran ara won lowo

[94] Won si maa taari gbogbo won sinu Ina; awon ati esu won

[95] ati awon omo ogun ’Iblis patapata

[96] (Awon alaigbagbo), nigba ti won ba n ba ara won jiyan ninu Ina, won a wi pe

[97] A fi Allahu bura, dajudaju awa kuku ti wa ninu isina ponnbele

[98] nigba ti a fi yin se akegbe fun Oluwa gbogbo eda

[99] Ko si ohun ti o si wa lona bi ko se awon (esu) elese

[100] Ko si si awon olusipe kan fun wa

[101] Ko tun si ore imule kan (fun wa)

[102] Ti o ba je pe ipada si ile aye wa fun wa ni, nigba naa awa iba wa ninu awon onigbagbo ododo

[103] Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

[104] Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

[105] Ijo (Anabi) Nuh pe awon Ojise ni opuro

[106] Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Nuh, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni

[107] Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

[108] Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[109] Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

[110] Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi.”

[111] Won wi pe: “Se ki a gba o gbo nigba ti o je pe awon eniyan yepere l’o n tele o!?”

[112] O so pe: “Emi ko nimo si ohun ti won n se (leyin mi)

[113] Ko si isiro-ise won lodo eni kan bi ko se lodo Oluwa mi, ti o ba je pe e ba fura

[114] Emi ko si nii le awon onigbagbo ododo danu

[115] Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele.”

[116] Won wi pe: “Dajudaju ti iwo Nuh ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa ju loko.”

[117] O so pe: “Oluwa mi, dajudaju awon eniyan mi ti pe mi ni opuro

[118] Nitori naa, sedajo taara laaarin emi ati awon. Ki o si la emi ati awon t’o wa pelu mi ninu awon onigbagbo ododo.”

[119] A la oun ati awon t’o wa pelu re ninu oko oju-omi t’o kun keke

[120] Leyin naa, A te awon t’o seku ri sinu omi

[121] Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

[122] Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

[123] Awon iran ‘Ad pe awon Ojise ni opuro

[124] Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Hud, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni

[125] Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

[126] Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[127] Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

[128] Se e oo maa ko ile nla nla si awon aye giga (ki e le) maa fi awon olurekoja sefe

[129] E si n ko awon ile nla nla bi eni pe e maa se gbere (nile aye yii)

[130] Nigba ti e ba si gba (eniyan mu lati fiya je won), e n gba won mu ni igbamu alailoju-aanu

[131] Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[132] E beru Eni ti O ran yin lowo pelu ohun ti e mo

[133] O ran yin lowo pelu awon eran-osin ati awon omo

[134] ati awon ogba oko pelu awon iseleru omi

[135] Dajudaju emi n paya iya ojo nla fun yin.”

[136] Won wi pe: “Bakan naa ni fun wa; yala o kilo fun wa tabi o o si ninu awon olukilo

[137] Eyi ko je kini kan bi ko se iwa awon eni akoko

[138] Won ko si nii je wa niya.”

[139] Nitori naa, won pe e ni opuro. A si pa won run. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

[140] Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

[141] Awon iran Thamud pe awon Ojise ni opuro

[142] Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Solih, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni

[143] Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

[144] Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[145] Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

[146] Se ki won fi yin sile sibi nnkan ti o wa (nile aye) nibi yii (ninu igbadun aye, ki e je) olufokanbale

[147] ninu awon ogba oko ati iseleru omi

[148] ati oko irugbin pelu igi dabinu ti ogomo re tutu

[149] E si n gbe awon ile sinu awon apata (gege bi) akose-mose

[150] Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[151] Ki e si ma se tele ase awon alaseju

[152] awon t’o n sebaje lori ile, ti won ko si se rere.”

[153] Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi

[154] Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Nitori naa, mu ami kan wa ti o ba wa ninu awon olododo.”

[155] O so pe: “Eyi ni abo rakunmi kan. Omi wa fun ohun, omi si wa fun eyin naa ni ojo ti a ti mo

[156] E ma se fi aburu kan kan an nitori ki iya ojo nla ma baa je yin.”

[157] Won si gun un pa. Nitori naa, won si di alabaamo

[158] Iya naa je won. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

[159] Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

[160] Ijo Lut pe awon Ojise ni opuro

[161] Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Lut, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni

[162] Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

[163] Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[164] Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

[165] Se awon okunrin ninu eda ni eyin okunrin yoo lo maa ba (fun adun ibalopo)

[166] E si n pa ohun ti Oluwa yin da fun yin ti ninu awon iyawo yin! Ani se, ijo alakoyo ni eyin.”

[167] Won wi pe: “Ti iwo Lut ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa le jade kuro ninu ilu.”

[168] O so pe: "Dajudaju emi wa ninu awon olubinu si ise (aburu) owo yin

[169] Oluwa mi, la emi ati awon eniyan mi nibi ohun ti won n se nise (aburu)

[170] Nitori naa, A la oun ati awon eniyan re patapata

[171] Afi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare)

[172] Leyin naa, A pa awon yooku run

[173] A ro ojo le won lori taara. Ojo awon ti A kilo fun si buru

[174] Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

[175] Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

[176] Awon ara ’Aekah pe awon Ojise ni opuro

[177] Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb, so pe: “Se eyin ko nii beru (Allahu) ni

[178] Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

[179] Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[180] Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda

[181] E won osuwon kun. Ki e si ma se wa ninu awon oludosuwonku

[182] E fi iwon t’o to won nnkan

[183] E ma se din nnkan awon eniyan ku. Ki e si ma se huwa aburu lori ile ni ti obileje

[184] Ki e si beru Eni ti O da yin ati awon iran akoko.”

[185] Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi

[186] Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Ati pe a o ro o si kini kan bi ko se pe o wa ninu awon opuro

[187] Nitori naa, je ki apa kan ninu sanmo ya lu wa mole, ti o ba wa ninu awon olododo.”

[188] O so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa ohun ti e n se nise

[189] Won si pe e ni opuro. Nitori naa, iya ojo esujo si je won. Dajudaju o je iya ojo nla

[190] Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo

[191] Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun

[192] Dajudaju al-Ƙur’an, won so o kale ni lati odo Oluwa gbogbo eda

[193] Molaika Jibril, olufokantan l’o so o kale

[194] sinu okan re nitori ki o le wa ninu awon olukilo

[195] pelu ede Larubawa ponnbele

[196] Dajudaju (oro nipa re) ti wa ninu ipin-ipin Tira awon eni akoko

[197] Se ko je ami kan fun won pe awon onimo (ninu) awon omo ’Isro’il nimo (si asoole nipa) re (ninu tira owo won)

[198] Ti o ba je pe A so o kale fun apa kan awon elede miiran ni

[199] ti o si ke e fun won, won ko nii gba a gbo ni ododo

[200] Bayen ni A se mu (atako) wo inu okan awon elese

[201] Won ko nii gba a gbo ni ododo titi won yoo fi ri iya eleta-elero

[202] (Iya naa) yoo de ba won ni ojiji; won ko si nii fura

[203] Nigba naa ni won yoo wi pe: "Nje won le lo wa lara bi

[204] Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju

[205] So fun Mi ti A ba fun won ni igbadun aye fun odun gbooro

[206] Leyin naa, ki ohun ti A n se ni adehun fun won de ba won

[207] Ohun ti A se ni igbadun fun won ko si nii ro won loro

[208] A o si pa ilu kan run afi ki won ti ni awon olukilo

[209] Iranti (de fun won se). Ati pe Awa ki i se alabosi

[210] Ki i se awon esu ni won so (al-Ƙur’an) kale

[211] Ko ye fun won. Won ko si lagbara re

[212] Dajudaju A ti mu won takete si gbigbo re (lati oju sanmo)

[213] Nitori naa, ma se pe olohun miiran mo Allahu, nitori ki iwo ma baa wa ninu awon ti A maa je niya

[214] Ki o si kilo fun awon ebi re, t’o sunmo julo

[215] Ki o si re apa re nile fun awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo

[216] Ti won ba si yapa (ase) re, so pe: “Dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n se (nise aburu).”

[217] Ki o si gbarale Alagbara, Asake-orun

[218] Eni t’O n ri o nigba ti o n dide naro (fun irun kiki)

[219] ati iyirapada re (fun rukuu ati iforikanle) laaarin awon oluforikanle

[220] Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo

[221] Se ki ng so eni ti awon esu n sokale wa ba

[222] Won n sokale wa ba gbogbo awon opuro, elese

[223] (Awon esu) n deti (si iro sanmo). Opolopo won si ni opuro

[224] Awon elewi, awon olusina l’o n tele won

[225] Se o o ri i pe gbogbo ogbun oro ni won n tenu bo ni

[226] Ati pe dajudaju won n so ohun ti won ko nii se

[227] Afi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se ise rere, ti won ranti Allahu ni opolopo, ti won si jaja gbara leyin ti won ti sabosi si won. Awon t’o sabosi si maa mo iru ikangun ti won maa gunle si

Kòkòrò

Surah 27

[1] To sin. Iwonyi ni awon ayah al-Ƙur’an ati (awon ayah) Tira t’o n yanju oro eda

[2] (O je) imona ati iro idunnu fun awon onigbagbo ododo

[3] awon t’o n kirun, ti won n yo zakah. Awon si ni won ni amodaju nipa Ojo Ikeyin

[4] Dajudaju awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo, A ti se awon ise (aburu owo) won ni oso fun won, Nitori naa, won yo si maa pa ridarida

[5] Awon wonyen ni awon ti iya buruku wa fun. Awon si ni eni ofo julo ni Ojo Ikeyin

[6] Dajudaju o n gba al-Ƙur’an lati odo Ologbon, Onimo

[7] (Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun awon eniyan re pe: “Dajudaju mo ri ina kan. Mo si maa lo mu iro kan wa fun yin lati ibe, tabi ki ng mu ogunna kan t’o n tanna wa fun yin nitori ki e le yena

[8] Nigba ti o de ibe, A pepe pe ki ibukun maa be fun eni ti o wa nibi ina naa ati eni ti o wa ni ayika re. Mimo si ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda

[9] Musa, dajudaju Emi ni Allahu, Alagbara, Ologbon

[10] Ju opa re sile. (O si se bee.) Amo nigba ti o ri i t’o n yira pada bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo. Ko si pada. (Allahu so pe:) Musa, ma se paya. Dajudaju awon Ojise ki i paya lodo Mi

[11] Ayafi eni ti o ba sabosi, leyin naa ti o yi i pada si rere leyin aburu. Dajudaju Emi ni Alaforijin, Asake-orun

[12] Ti owo re bo (abiya lati ibi) orun ewu re. O si maa jade ni funfun, ti ki i se ti aburu. (Eyi wa) ninu awon ami mesan-an (ti o maa mu lo) ba Fir‘aon ati awon eniyan re. Dajudaju won je ijo obileje

[13] Nigba ti awon ami Wa, t’o foju han kedere, si de ba won, won wi pe: “Eyi ni idan ponnbele.”

[14] Won tako o pelu abosi ati igberaga, emi won si ni amodaju pe ododo ni. Nitori naa, woye si bi atubotan awon obileje ti ri

[15] Dajudaju A fun (Anabi) Dawud ati (Anabi) Sulaemon ni imo. Awon mejeeji si so pe: "Ope ni fun Allahu, Eni ti O fun wa ni oore ajulo lori opolopo ninu awon erusin Re, awon onigbagbo ododo

[16] (Anabi) Sulaemon si jogun (Anabi) Dawud. O so pe: "Eyin eniyan, Won fi ohun eye mo wa. Won si fun wa ni gbogbo nnkan. Dajudaju eyi, ohun ni oore ajulo ponnbele

[17] A si ko jo fun (Anabi) Sulaemon, awon omo ogun re ninu alujannu, eniyan ati eye. A si n ko won jo papo mora won

[18] titi won fi de afonifoji awon awurebe. Awurebe kan si wi pe: "Eyin awurebe, e wo inu ile yin lo, ki (Anabi) Sulaemon ati awon omo ogun re ma baa te yin re mole. Won ko si nii fura

[19] Nigba naa, (Anabi Sulaemon) rerin-in muse, erin pa a nitori oro (awurebe naa). O so pe: “Oluwa mi, fi mo mi bi mo se maa dupe idera Re, eyi ti O fi se idera fun emi ati awon obi mi mejeeji. (Fi mo mi) bi mo se maa se ise rere, eyi ti O yonu si. Pelu aanu Re fi mi saaarin awon erusin Re, awon eni rere.”

[20] O sabewo awon eye, o si so pe: “Nitori ki ni mi o se ri eye hudhuda? Abi o je okan ninu awon ti ko wa ni

[21] Dajudaju mo maa je e niya lile, tabi ki ng dunbu re, tabi ki o mu eri t’o yanju wa fun mi.”

[22] (Anabi Sulaemon) ko duro pe (titi o fi de), o si wi pe: "Mo mo nnkan ti o o mo. Mo si mu iro kan t’o daju wa ba o lati ilu Saba’i

[23] Dajudaju emi ba obinrin kan (nibe), t’o n se ijoba le won lori. Won fun un ni gbogbo nnkan. O si ni ite nla kan

[24] Mo si ba oun ati awon eniyan re ti won n fori kanle fun oorun leyin Allahu. Esu si se awon ise won ni oso fun won. O seri won kuro loju ona (ododo). Nitori naa, won ko si mona

[25] lati fori kanle fun Allahu, Eni t’O n mu oro t’o pamo sinu awon sanmo ati ile jade, O si mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n safi han

[26] Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun, Oluwa Ite nla

[27] O so pe: "A maa woye boya ododo l’o so ni tabi o wa ninu awon opuro

[28] Mu iwe mi yii lo, ki o ju u si won. Leyin naa, ki o takete si won, ki o si wo ohun ti won yoo da pada (ni esi)

[29] (Bilƙis) so pe: “Eyin ijoye, dajudaju won ti ju iwe alapon-onle kan si mi

[30] Dajudaju o wa lati odo (Anabi) Sulaemon. Dajudaju o (so pe) “Ni oruko Allahu, Ajoke-aye, Asake-orun

[31] Ki e ma segberaga si mi, ki e si wa si odo mi (lati di) musulumi.”

[32] (Bilƙis) so pe: “Eyin ijoye, e gba mi ni imoran nipa oro mi. Emi ki i gbe igbese lori oro kan titi e maa fi jerii si i.”

[33] Won wi pe: “Alagbara ni awa. Akoni ogun si tun ni wa. Odo re ni oro wa. Nitori naa, woye si ohun ti o maa pa lase.”

[34] (Bilƙis) wi pe: “Dajudaju awon oba, nigba ti won ba wo inu ilu kan, won yoo ba a je. Won yo si so awon eni abiyi ibe di eni yepere. Bayen ni won maa n se

[35] Dajudaju mo maa fi ebun kan ranse si won. Mo si maa woye si ohun ti awon iranse yoo mu pada (ni esi).”

[36] Nigba ti (iranse) de odo (Anabi) Sulaemon, o so pe: “Se e maa fi owo ran mi lowo ni? Ohun ti Allahu fun mi loore julo si ohun ti e fun mi. Sibesibe, eyin tun n yo lori ebun yin

[37] Pada si odo won. Dajudaju a n bo wa ba won pelu awon omo ogun ti won ko le koju re. Dajudaju a maa mu won jade kuro ninu (ilu won) ni eni abuku. Won yo si di eni yepere.”

[38] (Anabi Sulaemon) so pe: “Eyin ijoye, ewo ninu yin l’o maa gbe ite (Bilƙis) wa ba mi, siwaju ki won to wa ba mi (lati di) musulumi.”

[39] ‘Ifrit ninu awon alujannu so pe: “Emi yoo gbe wa fun o siwaju ki o to dide kuro ni aye re. Dajudaju emi ni alagbara, olufokantan lori re.”

[40] Eni ti imo kan lati inu tira wa ni odo re so pe: “Emi yoo gbe e wa fun o siwaju ki o to seju.” Nigba ti o ri i ti o de si odo re, o so pe: “Eyi wa ninu oore ajulo Oluwa mi, lati fi dan mi wo boya mo maa dupe tabi mo maa sai moore. Enikeni ti o ba dupe (fun Allahu), o dupe fun emi ara re. Enikeni ti o ba si saimoore, dajudaju Oluwa mi ni Oloro, Alapon-onle.”

[41] O so pe: “E se iyipada irisi ite re fun un, ki a wo o boya o maa da a mo tabi o maa wa ninu awon ti ko nii da a mo.”

[42] Nigba ti (Bilƙis) de, won so fun un pe: “Se bi ite re se ri niyi?” O wi pe: "O da bi eni pe ohun ni." (Anabi Sulaemon si so pe): “Won ti fun wa ni imo siwaju Bilƙis. A si je musulumi.”

[43] Ohun t’o n josin fun leyin Allahu si seri re (kuro nibi ijosin fun Allahu). Dajudaju o wa ninu ijo alaigbagbo

[44] Won so fun un pe: “Wo inu aafin.” Nigba ti o ri i, o se bi ibudo ni. O si ka aso kuro ni ojugun re mejeeji. (Anabi Sulaemon) so pe: “Dajudaju aafin ti a se rigidin pelu dingi ni.” (Bilƙis) so pe: "Oluwa mi, dajudaju mo sabosi si emi ara mi. Mo si di musulumi pelu (Anabi) Sulaemon, fun Allahu, Oluwa gbogbo eda

[45] Dajudaju A ti ranse si ijo Thamud. (A ran) arakunrin won, Solih (nise si won), pe: "E josin fun Allahu." Nigba naa ni won pin si ijo meji, t’o n bara won jiyan

[46] O so pe: “Eyin ijo mi, nitori ki ni e se n wa (iya) aburu pelu ikanju siwaju (ohun) rere (t’o ye ki e mu se nise)? E o se toro aforijin lodo Allahu nitori ki Won le saanu yin?”

[47] Won wi pe: “A ri ami aburu lati odo re ati awon t’o wa pelu re.” (Anabi Solih) so pe: “Ami aburu yin wa (ninu kadara yin) lodo Allahu. Ko si ri bi e se ro o amo ijo aladan-anwo ni yin ni.”

[48] Awon eniyan mesan-an kan si wa ninu ilu, ti won n sebaje lori ile, ti won ko si se rere

[49] Won wi (funra won) pe: “Ki a dijo fi Allahu bura pe dajudaju a maa pa oun ati awon eniyan re ni oru. Leyin naa, dajudaju a maa so fun ebi re pe iparun awon eniyan re ko soju wa. Dajudaju olododo si ni awa.”

[50] Won dete gan-an, Awa naa si dete gan-an, won ko si fura

[51] Wo bi atubotan ete won ti ri. Dajudaju A pa awon ati ijo won run patapata

[52] Nitori naa, iwonyen ni ile won. O ti di ile ahoro nitori pe won sabosi. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o nimo

[53] A gba awon t’o gbagbo ni ododo la, ti won si n beru (Allahu)

[54] (A tun fi ise imisi ran Anabi) Lut. (Ranti) nigba ti o so fun ijo re pe: "Se ise aburu ni e oo maa se ni, e si riran

[55] Se dajudaju eyin (okunrin) yoo maa lo je adun (ibalopo) lara awon okunrin (egbe yin ni) dipo awon obinrin? Ani se, ope eniyan ni yin

[56] Ko si ohun kan ti ijo re fo ni esi tayo pe won wi pe: “E le awon eniyan Lut jade kuro ninu ilu yin. Dajudaju won je eniyan t’o n fora won mo (nibi ese).”

[57] Nitori naa, A gba oun ati ebi re la afi iyawo re; A ti ko o pe o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun

[58] A ro ojo le won lori taara. Ojo awon ti A kilo fun si buru

[59] So pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu. Ki alaafia maa ba awon erusin Re, awon ti O sa lesa. Se Allahu l’O loore julo ni tabi nnkan ti won n so di akegbe Re

[60] (Se iborisa l’o loore julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O da awon sanmo ati ile, ti O so omi kale fun yin lati sanmo, ti A si fi omi naa hu awon ogba oko ti o dara jade? Ko si si agbara fun yin lati mu igi re hu jade. Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Rara, ijo t’o n sebo si Allahu ni won ni

[61] (Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O se ile ni ibugbe, ti O fi awon odo saaarin re, ti O fi awon apata t’o duro sinsin sinu ile, ti O si fi gaga saaarin ibudo mejeeji? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Sibesibe opolopo won ni ko mo

[62] (Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O n jepe eni ti ara n ni nigba ti o ba pe E, ti O si maa gbe aburu kuro fun un, ti O si n se yin ni arole lori ile? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Die ni ohun ti e n lo ninu iranti

[63] (Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O n to yin sona ninu awon okunkun ori ile ati inu ibudo, ti O tun n fi ategun ranse ni iro idunnu siwaju ike Re? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Allahu ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[64] (Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O pile iseda eda, leyin naa, ti O maa da a pada (leyin iku), ti O si n pese fun yin lati sanmo ati ile? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? So pe: "E mu eri yin wa ti e ba je olododo

[65] So pe: “Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile ko nimo ikoko afi Allahu. Ati pe won ko si mo asiko wo ni A maa gbe awon oku dide.”

[66] Bee ni, ni orun ni imo won maa to mo Ojo Ikeyin (loran). Bee ni, won wa ninu iyemeji nipa re (bayii). Bee ni, won ti fonu-fora nipa re

[67] Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Se nigba ti awa ati awon baba wa ba ti di erupe, se (nigba naa ni) won yoo mu wa jade

[68] Won kuku ti se adehun eyi fun awa ati awon baba wa teletele. Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko.”

[69] So pe: “E rin kiri lori ile, ki e wo bi atubotan awon elese se ri.”

[70] Ma se banuje nitori won. Ma si je ki ohun ti won n da ni ete ko inira ba o

[71] Won n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo.”

[72] So pe: “O le je pe apa kan ohun ti e n wa pelu ikanju ti sunmo yin tan.”

[73] Dajudaju Oluwa re ma ni Olola lori awon eniyan, sugbon opolopo won ki i dupe (fun Un)

[74] Dajudaju Oluwa re, O kuku mo ohun ti igba-aya won n gbe pamo ati ohun ti won n safi han re

[75] Ati pe ko si ohun ikoko kan ninu sanmo ati ile afi ki o wa ninu akosile t’o han kedere

[76] Dajudaju al-Ƙur’an yii yoo maa salaye oro fun awon omo ’Isro’il nipa opolopo ohun ti won n yapa enu si

[77] Ati pe dajudaju imona ati ike ni fun awon onigbagbo ododo

[78] Dajudaju Oluwa re maa se idajo laaarin won pelu idajo Re. Oun ni Alagbara, Onimo

[79] Nitori naa, gbarale Allahu. Dajudaju iwo wa lori ododo ponnbele

[80] Dajudaju iwo ko l’o maa mu awon oku gboro. O o si nii mu awon aditi gbo ipe nigba ti won ba keyin si o, ti won n lo

[81] Iwo ko l’o maa fi ona mo awon afoju nibi isina won. Ko si eni ti o maa mu gbo oro afi eni ti o ba gba awon ayah Wa gbo nitori pe awon ni (musulumi) olujupa-juse-sile fun Allahu

[82] Nigba ti oro naa ba ko le won lori, A maa mu eranko kan jade fun won lati inu ile, ti o maa ba won soro pe: “Dajudaju awon eniyan ki i nimo amodaju nipa awon ayah Wa.”

[83] Ati pe (ranti) ojo ti A oo ko ijo kan jo ninu ijo kookan ninu awon t’o n pe awon ayah Wa niro. A o si ko won jo papo mora won

[84] Titi (di) igba ti won ba de (tan), (Allahu) yoo so pe: "Se e pe awon ayah Mi niro, ti eyin ko si ni imo kan nipa re (ti e le fi ja a niro)? Tabi ki ni e n se nise (nile aye)

[85] Oro naa si ko le won lori nitori pe won sabosi. Won ko si nii soro

[86] Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A da oru nitori ki won le sinmi ninu re, (A si da) osan (nitori ki won le) riran? Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo

[87] (Ranti) ojo ti won a fon fere oniwo, gbogbo eni ti o wa ninu sanmo ati ile yo si jaya afi eni ti Allahu ba fe. Gbogbo eda l’o si maa yepere wa ba Allahu

[88] O si maa ri awon apata, ti o lero pe nnkan gbagidi t’o duro soju kan naa ni, ti o maa rin irin esujo. (Iyen je) ise Allahu, Eni ti O se gbogbo nnkan ni daadaa. Dajudaju O mo ikoko ohun ti e n se nise

[89] Enikeni ti o ba mu ise rere wa, tire ni rere t’o loore julo si eyi t’o mu wa. Awon si ni olufayabale ninu ijaya ojo yen

[90] Enikeni ti o ba si mu (ise) aburu wa, A si maa da oju won bole ninu Ina. Nje A oo san yin ni esan kan bi ko se ohun ti e n se nise

[91] Ohun ti won pa mi ni ase re ni pe ki ng josin fun Oluwa Ilu yii, Eni ti O se e ni aye owo. TiRe si ni gbogbo nnkan. Won si pa mi ni ase pe ki ng wa ninu awon musulumi

[92] Ati pe ki ng maa ke al-Ƙur’an. Nitori naa, enikeni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni ti o ba si sina, so pe: “Dajudaju emi wa ninu awon olukilo.”

[93] So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu.” (Allahu) yoo fi awon ami Re han yin. Eyin yo si mo won. Oluwa re ko si gbagbe ohun ti e n se nise

Àwọn Ìtàn

Surah 28

[1] To sin mim

[2] Iwonyi ni awon ayah Tira t’o n yanju oro eda

[3] A n ke ninu iro (Anabi) Musa ati Fir‘aon fun o pelu ododo nitori ijo t’o gbagbo lododo

[4] Dajudaju Fir‘aon segberaga lori ile. O se awon eniyan re ni ijo-ijo. O n da igun kan ninu won lagara; o n pa awon omokunrin won, o si n da awon obinrin won si. Dajudaju o wa ninu awon obileje

[5] A si fe sedera fun awon ti won foju tinrin lori ile, A (fe) se won ni asiwaju. A si (fe) ki won jogun (ile)

[6] A (fe) gba won laaye lori ile. Lati ara won, A si (fe) fi han Fir‘aon ati Hamon pelu awon omo ogun awon mejeeji ohun ti won n sora fun lara won

[7] A si ranse si iya (Anabi) Musa pe: “Fun un ni omu mu. Ti o ba si n paya lori re, ju u sinu agbami odo. Ma se beru. Ma si se banuje. Dajudaju Awa maa da a pada si odo re. A o si se e ni ara awon Ojise

[8] Nigba naa, awon eniyan Fir‘aon ri i he nitori ki o le je ota ati ibanuje fun won. Dajudaju Fir‘aon, Hamon ati awon omo ogun awon mejeeji, won je alasise

[9] Iyawo Fir‘aon wi pe: “Itutu-oju ni (omo yii) fun emi ati iwo. E ma se pa a. O le je pe o maa se wa ni anfaani tabi ki a fi se omo.” Won ko si fura

[10] Okan iya (Anabi) Musa pami (lori oro Musa, ko si ri nnkan miiran ro mo tayo re) o kuku fee safi han re (pe omo oun ni nigba ti won pe e de odo Fir‘aon) ti ko ba je pe A ki i lokan nitori ki o le wa ninu awon onigbagbo ododo

[11] O si so fun arabinrin re pe: “Topa re lo.” O si n wo o lati ibi t’o jinna. Won ko si fura (si i)

[12] A ko si je ki o mu oyan (miiran) siwaju (tiya re.) Arabinrin re si wi pe: “Se ki ng fi ara ile kan han yin, ti o maa gba a to fun yin? Won yo si je olutoju re.”

[13] A si da a pada si odo iya re nitori ki oju re le tutu (fun idunnu) ati nitori ki o ma baa banuje. Ati pe nitori ki o le mo pe dajudaju adehun Allahu, ododo ni, sugbon opolopo won ni ko mo

[14] Nigba t’o dagba, t’o di gende, A fun un ni ogbon ati imo. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan

[15] O wo inu ilu nigba ti awon ara ilu ti gbagbe (nipa oro re). O ri awon okunrin meji kan ti won n ja. Eyi wa lati inu iran re. Eyi si wa lati (inu iran) ota re. Eyi ti o wa lati inu iran re wa iranlowo re lori eyi ti o wa lati (inu iran) ota re. Musa kan an ni ese. O si pa a. O so pe: “Eyi wa ninu ise Esu. Dajudaju (esu) ni ota asini-lona ponnbele.”

[16] O so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi ti sabosi si emi ara mi. Nitori naa, forijin mi.” O si forijin in. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun

[17] O so pe: “Oluwa mi, fun wi pe O ti se ike fun mi, emi ko nii je oluranlowo fun awon elese.”

[18] Nitori naa, o di eni t’o n beru ninu ilu, o si n reti (ehonu iran Fir‘aon). Nigba naa ni eni ti o wa iranlowo re ni ana tun n logun re fun iranlowo re. Musa so fun un pe: “Dajudaju iwo ni olusina ponnbele.”

[19] Amo nigba ti o fe gba eni ti o je ota fun awon mejeeji mu, eni naa wi pe: “Musa, se o fe pa mi bi o se pa eni kan ni ana? O o gbero kan tayo ki o je alailoju-aanu lori ile; o o si gbero lati wa ninu awon alatun-unse.”

[20] Okunrin kan sare de lati opin ilu naa, o wi pe: “Musa, dajudaju awon ijoye n da imoran lori re lati pa o. Nitori naa, jade (kuro ninu ilu), dajudaju emi wa ninu awon onimoran rere fun o.”

[21] O si jade kuro ninu (ilu) pelu ipaya, ti o n reti (ehonu won), o si so pe: “Oluwa mi, la mi lowo ijo alabosi.”

[22] Nigba ti o si doju ko okankan ilu Modyan, o so pe: “O sunmo ki Oluwa mi fona taara (si ilu Modyan) mo mi.”

[23] Nigba ti o de ibi (kannga) omi (ilu) Modyan, o ba ijo eniyan kan nibe ti won n fun awon eran-osin won ni omi mu. Leyin won, o tun ri awon obinrin meji kan ti won n fa seyin (pelu eran-osin won). O so pe: “Ki l’o se eyin mejeeji?” Won so pe: “A o le fun awon eran-osin wa ni omi mu titi awon adaran ba to ko awon eran-osin won lo. Agbalagba arugbo si ni baba wa.”

[24] O si ba won fun (eran-osin) won ni omi mu. Leyin naa, o pada sibi iboji, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi bukata si ohun ti O ba sokale fun mi ninu oore.”

[25] Okan ninu awon mejeeji wa ba a, o si n rin pelu itiju, o so pe: “Dajudaju baba mi n pe o nitori ki o le san o ni esan omi ti o fun (awon eran-osin) wa mu.” Nigba ti o de odo re, o so itan (ara re) fun un. (Baba naa) so pe: “Ma beru. O ti la lowo ijo alabosi.”

[26] Okan ninu (awon omobinrin) mejeeji so pe: “Baba mi o, gba a sise. Dajudaju eni t’o dara julo ti o le gba sise ni alagbara, olufokantan.”

[27] O so pe: “Dajudaju mo fe fi okan ninu awon omobinrin mi mejeeji wonyi fun o ni aya lori (adehun) pe o maa ba mi sise fun odun mejo. Sugbon ti o ba se e pe odun mewaa, lati odo re niyen. Emi ko si fe ko inira ba o. Ti Allahu ba fe, o maa ri i pe mo wa ninu awon eni rere.”

[28] (Musa) so pe: “(Adehun) yii wa laaarin emi ati iwo. Eyikeyii ti mo ba mu se ninu adehun mejeeji naa, iwo ko gbodo sabosi si mi. Allahu si ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).”

[29] Nigba ti Musa pari akoko naa, o mu ara ile re rin (irin-ajo). O si ri ina kan ni eba apata. O so fun ara ile re pe: “E duro (sibi na). Emi ri ina kan. O se e se ki ng mu iro kan wa ba yin lati ibe tabi (ki ng mu) ogunna kan wa nitori ki e le ri ohun yena.”

[30] Nigba ti o de ibe, A pe e lati egbe afonifoji ni owo otun (re) ni aye ibukun lati ibi igi naa. (A so pe): “Musa, dajudaju Emi ni Allahu, Oluwa gbogbo eda

[31] Ju opa re sile.” (O si ju u sile). Nigba ti o ri i t’o n mira bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo, ko si pada. (Allahu so pe): “Musa, maa bo pada, ma si se paya. Dajudaju iwo wa ninu awon olufayabale

[32] Ti owo re bo (abiya lati ibi) orun ewu re, o si maa jade ni funfun ti ki i se ti aburu. Pa owo re mora si (abiya re) nibi eru. Nitori naa, awon eri meji niwonyi lati odo Oluwa re si Fir‘aon ati awon ijoye re. Dajudaju won je ijo obileje.”

[33] (Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi pa eni kan ninu won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi

[34] Ati pe arakunrin mi, Harun, o da lahon ju mi lo. Nitori naa, ran an nise pelu mi, ki o je oluranlowo ti yoo maa jerii si ododo oro mi. Dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro.”

[35] (Allahu) so pe: “A maa fi arakunrin re kun o lowo. A o si fun eyin mejeeji ni agbara, won ko si nii le de odo eyin mejeeji. Pelu awon ami Wa, eyin mejeeji ati awon t’o ba tele eyin mejeeji l’o maa bori.”

[36] Nigba ti (Anabi) Musa de ba won pelu awon ami Wa, won wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan adahun. A ko si gbo eyi (ri) laaarin awon baba wa, awon eni akoko.”

[37] (Anabi) Musa si so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa eni ti o mu imona wa lati odo Re ati eni ti atubotan ile (ike) maa je tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”

[38] Fir‘aon wi pe: “Eyin ijoye, emi ko mo pe olohun kan tun wa leyin mi! Nitori naa, Hamon, da ina fun mi, ki o fi mo amo, ki o si ko ile giga kan fun mi nitori ki emi le yoju wo Olohun Musa. (Nitori pe) dajudaju mo n ro o si ara awon opuro.”

[39] Oun ati awon omo ogun re si segberaga lori ile lai letoo. Won si ro pe dajudaju A o nii da won pada si odo Wa

[40] Nitori naa, A gba oun ati awon omo ogun re mu; A ju won sinu agbami odo. Wo bi atubotan awon alabosi ti ri

[41] A se won ni asiwaju t’o n pepe sinu Ina. Ti o ba si di Ojo Ajinde, A o nii ran won lowo

[42] Ati pe A fi egun topa won ni ile aye yii. Ni Ojo Ajinde, won yo si wa ninu awon eni iparun

[43] Dajudaju A ti fun (Anabi) Musa ni Tira leyin igba ti A ti pa awon ijo akoko re. (Tira naa je) ariwoye fun awon eniyan, imona ati ike nitori ki won le lo iranti

[44] Iwo ko si ni eba iwo-oorun nigba ti A fi oro naa ranse si (Anabi) Musa. Ati pe iwo ko si ninu awon t’o wa nibe

[45] Sugbon A seda awon iran kan ti emi won gun. O o kuku gbe laaarin ara ilu Modyan, ti o n ke awon ayah Wa fun won, sugbon Awa l’a n ran awon Ojise nise

[46] (Iwo ko si si ni eba apata, nigba ti A pepe, sugbon o je ike kan lati odo Oluwa re nitori ki o le sekilo fun awon eniyan ti olukilo kan ko wa ba ri siwaju re nitori ki won le lo iranti. 16:36 ati surah Fatir 35:24) bee naa l’a ri awon ayah miiran t’o n fi rinle pe Allahu ko ran Ojise tabi Anabi kan ri si awon Larubawa (gege bi o se rinle ninu surah al-Ƙosos ko si Ojise kan ti Allahu gbe dide laaarin won si gbogbo iran won ni apapo. Bi o tile je pe awon Larubawa ni anfaani lati gbo nipa Anabi ’Ibrohim ati omo re Anabi ’Ismo‘il pe Allahu ran won nise si awon eniyan kan amo ko si oye atinuwa fun imo nipa bi won maa se josin fun Allahu Eledaa won afi ki won ni Ojise kan t’o maa je asiwaju fun won gege bi olukoni rere. Idi niyi ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) fi gbe Anabi Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) dide ni ara oto. Itumo “ni ara oto” ni pe

[47] Ti o ba je pe adanwo kan kan won nitori ohun ti won fi owo won ti siwaju, won iba wi pe: “Oluwa wa, ti O ba je pe O ran Ojise kan si wa ni, a a ba tele awon ayah Re, a a ba si wa ninu awon onigbagbo ododo.”

[48] Sugbon nigba ti ododo de ba won lati odo Wa, won wi pe: "Ki ni ko je ki Won fun un ni iru ohun ti Won fun (Anabi) Musa?" Se won ko si sai gbagbo ninu ohun ti A fun (Anabi) Musa siwaju bi? Won wi pe: “Opidan meji t’o n ranra won lowo (ni won).” Won si tun wi pe: “Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ikookan (won).”

[49] So pe: “Nitori naa, e mu tira kan wa lati odo Allahu, t’o n to ni si ona ju ti awon mejeeji lo, mo si maa tele e, ti e ba je olododo.”

[50] Ti won ko ba jepe re, mo pe won kan n tele ife-inu won ni. Ta l’o si sina ju eni t’o tele ife-inu re, lai si imona (fun un) lati odo Allahu! Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

[51] Ati pe dajudaju A ti se alaye oro naa fun won nitori ki won le lo iranti

[52] Awon ti A fun ni Tira siwaju re, won gba al-Ƙur’an gbo

[53] Ati pe nigba ti won ba n ke e fun won, won a so pe: “A gba a gbo. Dajudaju ododo ni lati odo Oluwa wa. Dajudaju awa ti je musulumi siwaju re.”

[54] Awon wonyen ni A maa fun won ni esan won ni ee meji nitori pe won se suuru, won si n fi daadaa ti aidaa danu. Ati pe won n na ninu ohun ti A pese fun won

[55] Ati pe nigba ti won ba gbo oro buruku, won a seri kuro nibe, won a si so pe: “Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Ki alaafia maa ba yin. A ko wa awon alaimokan (ni alabaasepo).”

[56] Dajudaju iwo ko le fi ona mo eni ti o feran, sugbon Allahu l’O n fi ona mo eni ti O ba fe. Ati pe O nimo julo nipa awon olumona

[57] Won wi pe: “Ti a ba (fi le) tele imona pelu re, awon osebo yoo ko wa kuro lori ile wa.” Se A o fun won ni ibugbe (ti o je) aye owo ifokanbale, ti won si n ko awon eso gbogbo ilu wa sibe, ti o je ese lati odo Wa? Sugbon opolopo won ni ko mo

[58] Meloo meloo ninu ilu ti A pare, ti won yo ayoporo aye-jije ninu ilu. Iwonyen ni awon ibugbe won, ti A ko je ki eni kan kan gbe ibe leyin won bi ko se fun igba die. Awa si je Olujogun

[59] Oluwa re ko si nii pa awon ilu run (ni asiko tire yii) titi O fi maa gbe Ojise kan dide ninu Olu-ilu-aye (iyen, ilu Mokkah, eni ti) yoo maa ke awon ayah Wa fun won. (O si ti se bee.) A o si nii pa awon ilu (yii) run se afi ki awon ara ibe je alabosi

[60] Ko si ohun ti A fun yin bi ko se nitori igbadun aye ati oso re. Ohun t’o n be lodo Allahu loore julo, o si maa wa titi laelae. Nitori naa, se e o nii se laakaye ni

[61] Nje eni ti A ba sadehun ni adehun t’o dara, ti o si maa pade re, da bi eni ti A fun ni igbadun isemi aye bi, leyin naa ni Ojo Ajinde ti o maa wa ninu awon ti won yoo mu wa (fun iya Ina)

[62] (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Nibo ni awon akegbe Mi ti e n so nipa won lai ni eri lowo wa?”

[63] Awon ti oro naa ko le lori wi pe: “Oluwa wa, awon wonyi ti a ko sina, a ko won sina gege bi awa naa se sina. A yowo yose (ninu oro won) niwaju Re (bayii); ki i se awa ni won n josin fun.”

[64] A so (fun won) pe: “E pe awon orisa yin.” Won si pe won, sugbon won ko da won lohun. Won ti ri Ina. Ti o ba je pe dajudaju won je olumona ni (iya iba ti je won)

[65] (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Ki ni e fo ni esi fun awon Ojise?”

[66] Esi oro yo si foju po mo won lowo ni ojo yen; won ko si nii bira won leere ibeere

[67] Sugbon ni ti eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere, o sunmo pe o maa wa ninu awon olujere

[68] Oluwa re l’O n seda ohun ti O ba fe. O si n sa (ohun ti O ba fe) ni esa. Sisa esa ko to si won. Mimo ni fun Allahu. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[69] Oluwa re si mo ohun ti igba-aya won n fi pamo ati ohun ti won n se afihan re

[70] Oun si ni Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. TiRe ni ope ni ile aye yii ati ni orun. TiRe si ni idajo. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

[71] So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so oru di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni imole? Se e o gboro ni?”

[72] So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba so osan di ohun ti o maa wa titi laelae fun yin di Ojo Ajinde, olohun wo leyin Allahu l’o maa fun yin ni ale ti e oo maa sinmi ninu re? Se e o riran ni?”

[73] Ninu ike Re (ni pe) O se oru ati osan fun yin; nitori ki e le sinmi ninu (oru) ati nitori ki e le wa ninu oore Re (ni osan) ati nitori ki e le dupe

[74] (Ranti) ojo ti (Allahu) yoo pe won, O si maa so pe: “Nibo ni awon akegbe Mi ti e n so nipa won lai ni eri lowo wa?”

[75] A si maa mu elerii kan jade ninu ijo kookan. A maa so pe: “E mu idi oro yin wa.” Nigba naa, won yoo mo pe dajudaju ododo n je ti Allahu. Ohun ti won si n da ni adapa iro yo si dofo mo won lowo

[76] Dajudaju Ƙorun wa ninu ijo (Anabi) Musa, sugbon o segberaga si won. A si fun un ni awon apoti-oro eyi ti awon kokoro re wuwo lati gbe fun opo eniyan, awon alagbara. (Ranti) nigba ti awon eniyan re so fun un pe: "Ma se yo ayo ayoju. Dajudaju Allahu ko feran awon alayoju

[77] Fi nnkan ti Allahu fun o wa ile Ikeyin. Ma se gbagbe ipin re ni ile aye. Se daadaa gege bi Allahu ti se daadaa fun o. Ma si se wa ibaje se lori ile. Dajudaju Allahu ko feran awon obileje

[78] O wi pe: "Dajudaju won fun mi pelu imo t’o n be lodo mi ni." Se ko mo pe dajudaju Allahu ti parun ninu awon iran t’o siwaju re, eni ti o lagbara ju u lo, ti o si ni akojo oro ju u lo? A o si nii bi awon arufin leere (ese won. O kuku ti wa ni akosile)

[79] O jade si awon eniyan re pelu oso re. Awon t’o n fe isemi aye yii si wi pe: “Haa! Ki a si ni iru ohun ti won fun Ƙorun. Dajudaju o ni ipin nla ninu oore.”

[80] Awon ti A fun ni imo so pe: “Egbe ni fun yin! Esan Allahu loore julo fun eni t’o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Ko si si eni ti o maa ri (esan naa) gba afi awon onisuuru.”

[81] Nitori naa, A je ki ile gbe oun ati ile re mi. Ko ni ijo kan ti o le ran an lowo leyin Allahu. Ko si si ninu awon t’o le ran ara re lowo

[82] Awon t’o n rankan ipo re ni ana si bere si wi pe: “Se e ri i pe dajudaju Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. O si n diwon re (fun elomiiran). Ti ko ba je pe Allahu ke wa ni, iba je ki ile gbe awa naa mi ni. Se e ri i pe awon alaimoore ko nii jere.”

[83] Ile Ikeyin yen, A maa fi fun awon ti ko fe maa se igberaga ati ibaje lori ile. Igbeyin rere si wa fun awon oluberu (Allahu)

[84] Enikeni ti o ba mu ise rere wa, tire ni rere t’o loore julo si eyi t’o mu wa. Enikeni ti o ba si mu ise aburu wa, A o si nii san awon t’o se ise aburu ni esan kan afi ohun ti won n se nise

[85] Dajudaju Eni ti O se al-Ƙur’an ni oran-anyan fun o, O si maa da o pada si ebute kan. So pe: “Oluwa mi nimo julo nipa eni ti o mu imona wa ati ta ni o wa ninu isina ponnbele.”

[86] Iwo ko si reti pe A oo so tira al-Ƙur’an kale fun o (tele), amo o je ike kan lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo je alatileyin fun awon alaigbagbo

[87] Ma se je ki won se o lori kuro nibi awon ayah Allahu leyin igba ti A ti so o kale fun o. Pepe si odo Oluwa re. Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo

[88] Ma se pe olohun miiran mo Allahu. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Gbogbo nnkan l’o maa parun afi Oju Re (afi Oun). TiRe ni idajo. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

Alángbá

Surah 29

[1] ’Alif lam mim

[2] Nje awon eniyan lero pe A oo fi won sile ki won maa so pe: “A gbagbo”, ti A o si nii dan won wo

[3] A kuku ti dan awon t’o siwaju won wo. Nitori naa, dajudaju Allahu maa safi han awon t’o so ododo. Dajudaju O si maa safi han awon opuro

[4] Abi awon t’o n se ise aburu lero pe awon maa mori bo mo Wa lowo ni? Ohun ti won n da lejo buru

[5] Enikeni ti o ba n reti ipade Allahu, dajudaju akoko Allahu kuku n bo. Oun si ni Olugbo, Onimo

[6] Enikeni ti o ba gbiyanju, o n gbiyanju fun emi ara re ni. Dajudaju Allahu ni Oloro ti ko bukata si gbogbo eda

[7] Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa ha awon ise aburu won danu fun won. Dajudaju A o si san won lesan pelu eyi t’o dara ju ohun ti won n se

[8] A pa a ni ase fun eniyan lati se daadaa si awon obi re mejeeji. Ti awon mejeeji ba si ja o logun pe ki o fi ohun ti iwo ko ni imo nipa re sebo si Mi, ma se tele awon mejeeji. Odo Mi ni ibupadasi yin. Nitori naa, Mo maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

[9] Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon eni rere

[10] O n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “A gba Allahu gbo.” Nigba ti won ba si fi inira kan won ninu esin Allahu, o maa so inira eniyan da bi iya ti Allahu. Ti aranse kan lati odo Oluwa re ba si de, dajudaju won yoo wi pe: “Dajudaju awa wa pelu yin.” Se Allahu ko l’O nimo julo nipa ohun ti n be ninu igba-aya gbogbo eda ni

[11] Dajudaju Allahu maa safi han awon t’o gbagbo ni ododo. O si maa safi han awon sobe-selu musulumi

[12] Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo ni ododo pe: “E tele oju ona tiwa nitori ki a le ru awon ese yin.” Won ko si le ru kini kan ninu ese won. Dajudaju opuro ma ni won

[13] Dajudaju won yoo ru eru ese tiwon ati awon eru ese kan mo eru ese tiwon. Ati pe dajudaju A oo bi won leere ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n da ni adapa iro

[14] Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O gbe laaarin won fun egberun odun afi aadota odun. Ekun-omi si gba won mu nigba ti won je alabosi

[15] A si la oun ati awon ero inu oko oju-omi. A si se won ni ami fun gbogbo eda

[16] (Ranti Anabi) ’Ibrohim. Nigba ti o so fun ijo re pe: “E josin fun Allahu. Ki e si paya Re. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo.”

[17] E kan n josin fun awon orisa leyin Allahu. E si n da adapa iro. Dajudaju awon ti e n josin fun leyin Allahu, won ko ni ikapa arisiki kan fun yin. E wa arisiki si odo Allahu. Ki e josin fun Un. Ki e si dupe fun Un. Odo Re ni won yoo da yin pada si

[18] Ti e ba si pe (ododo) niro, awon ijo kan t’o siwaju yin kuku ti pe (ododo) niro. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele

[19] Tabi won ko ri bi Allahu ti se bere eda ni? Leyin naa, O maa da a pada (si odo Re). Dajudaju iyen rorun fun Allahu

[20] So pe: “E rin kiri lori ile, ki e wo bi O se bere eda (ni ipile). Leyin naa, Allahu l’O maa mu iseda ikeyin wa (fun ajinde). Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan.”

[21] O n je eni ti O ba fe niya. O si n ke eni ti O ba fe. Odo Re si ni won yoo da yin pada si. o je ohun ti Allahu fe bee fun eda naa ninu kadara re nitori pe tibi-tire ni kadara eda. Fifebee yii ni a n pe ni ""mosi’atu-llahi al-kaoniyyah"" “fifebee Allahu taye”. Bi apeere lagbaja fe di olowo lona eto o je ohun ti Allahu fe bee fun eda ninu ofin ati ilana Re. Allahu ko si nii fe ofin ati ilana kan bee ninu Tira Re t’o sokale fun wa afi ki o je rere ponnbele tabi ki rere re tewon ju aburu re lo. Fifebee yii ni a n pe ni ""mosi’atu-llahi as-ser‘iyyah"" “fifebee Allahu tofin”. Bi apeere lagbaja fe di musulumi mejeeji l’o duro sori “ ‘adl” ati “ fodl” – deede ati ola. Alaye eyi ni pe ti iya ba je lagbaja nile aye tabi ni orun lai je onigbagbo ododo enu eni keni ko gba a lati fi esun kan Allahu lori fifebee Re lori eda re. Sebi nile aye yii gan-an

[22] Ati pe eyin ko nii mori bo mo Allahu lowo lori ile ati ninu sanmo. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu

[23] Awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu ati ipade Re (lorun), awon wonyen ti soreti nu ninu ike Mi. Awon wonyen ni iya eleta-elero n be fun

[24] Esi ijo re ko je kini kan tayo pe won wi pe: “E pa a tabi ki e sun un nina.” Allahu si la a ninu ina. Dajudaju awon ami kuku wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo lododo

[25] O si so pe: “E kan mu awon orisa leyin Allahu, ni ohun ti e nifee si (lati josin fun) laaarin ara yin ninu isemi aye (yii). Leyin naa, ni Ojo Ajinde apa kan yin yoo tako apa kan. Apa kan yin yo si sebi le apa kan. Ina si ni ibugbe yin. Ko si nii si awon alaranse kan fun yin.”

[26] (Anabi) Lut si gba a gbo. (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Dajudaju emi yoo fi ilu yii sile nitori ti Oluwa mi. Dajudaju Oun ni Alagbara, Ologbon

[27] A fi ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (omoomo re) ta a lore. A si se jije Anabi ati fifunni ni tira sinu aromodomo re. A fun un ni esan re ni aye yii. Dajudaju ni orun, o tun wa ninu awon eni rere

[28] (Ranti Anabi) Lut. Nigba ti o so fun ijo re pe: “Dajudaju eyin n se ibaje ti ko si eni kan ninu eda ti o se e ri siwaju yin

[29] Se dajudaju eyin (okunrin) yoo maa to awon okunrin (egbe yin) lo (fun adun ibalopo), e tun n dana, e tun n se ohun buruku ninu akojo yin? Esi ijo re ko je kini kan afi ki won wi pe : “Mu iya Allahu wa fun wa ti o ba wa ninu awon olododo.”

[30] O so pe: “Oluwa mi, saranse fun mi lori ijo obileje.”

[31] Nigba ti awon Ojise Wa si mu iro idunnu de ba (Anabi) ’Ibrohim, won so pe: “Dajudaju awa maa pa awon ara ilu yii run. Dajudaju awon ara ilu naa je alabosi.”

[32] O so pe: “Dajudaju (Anabi) Lut wa nibe! Won so pe: “Awa nimo julo nipa awon t’o wa nibe. Dajudaju awa yoo la oun ati awon ara ile re afi iyawo re ti o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun.”

[33] Nigba ti awon Ojise Wa de odo (Anabi) Lut, o banuje nitori won. Agbara re ko si ka oro won mo. Won si so fun un pe: “Ma beru, ma si se banuje. Dajudaju a maa la iwo ati awon ara ile re afi iyawo re ti o maa wa ninu awon oluseku-leyin sinu iparun.”

[34] Dajudaju a maa so iya kan kale le awon ara ilu yii lori lati inu sanmo nitori pe won je obileje

[35] Dajudaju A ti fi ami kan t’o foju han lele ninu re fun ijo t’o ni laakaye

[36] A tun ranse si ara ilu Modyan. (A ran) arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb (nise si won). O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E reti Ojo Ikeyin, ki e si ma sebaje lori ile ni ti obileje.”

[37] Won pe e ni opuro. Nitori naa, ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won

[38] (A tun ranse si awon) ara ‘Ad ati ara Thamud. (Iparun won) si kuku ti foju han kedere si yin ninu awon ibugbe won. Esu se awon ise won ni oso fun won. O si seri won kuro ninu esin (Allahu). Won si je oluriran (nipa oro aye)

[39] (A tun ranse si awon) Ƙorun, Fir‘aon ati Hamon. Dajudaju (Anabi) Musa mu awon eri t’o yanju wa ba won. Won si segberaga lori ile. Won ko si le mori bo ninu iya

[40] A si mu ikookan won nipa ese re. O wa ninu won, eni ti A fi okuta ina ranse si. O wa ninu won eni ti igbe lile gba mu. O wa ninu won eni ti A je ki ile gbemi. O si wa ninu won eni ti A teri sinu omi. Allahu ko si nii sabosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

[41] Apejuwe awon t’o mu awon (orisa) ni alatileyin leyin Allahu, o da bi apejuwe alantaakun ti o ko ile kan. Dajudaju ile ti o yepere julo ni ile alantaakun, ti won ba mo

[42] Dajudaju Allahu mo ohunkohun ti won n pe leyin Re. Oun si ni Alagbara, Ologbon

[43] Awon akawe wonyi, ti A n fun awon eniyan, ko si si eni ti o maa se laakaye nipa re afi awon onimo

[44] Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun awon onigbagbo ododo

[45] Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira. Ki o si kirun. Dajudaju irun kiki n ko iwa ibaje ati aburu. Ati pe iranti Allahu tobi julo. Allahu si mo ohun ti e n se. bi irun kiki se ni esan bee naa lo tun je ohun t’o n mu olukirun jinna si iwa aburu aawe gbigba ati bee bee lo. Enikeni ti o ba pa irun kiki ati aawe gbigba ti nipase fifun gbolohun yii ni itumo odi o ti ko iparun ba emi ara re ni ibamu si surah al-Muddaththir; 74: 42-43. Ki Allahu (subhanahu wa ta'ala) la wa ninu eyi

[46] E ma se ba ahlul-kitab sariyan jiyan afi ni ona t’o dara julo (eyi ni lilo al-Ƙur’an ati hadith. E ma si se ja won logun) afi awon t’o ba sabosi ninu won. Ki e si so pe: “A gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun awa ati ohun ti Won sokale fun eyin. Olohun wa ati Olohun yin, (Allahu) Okan soso ni. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.”

[47] Bayen ni A se so Tira kale fun o. Nitori naa, awon ti A fun ni Tira, won gba a gbo. O si wa ninu awon wonyi (iyen, awon ara Mokkah), eni t’o gba a gbo. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alaigbagbo

[48] Iwo ko ke tira kan ri siwaju al-Ƙur’an, iwo ko si fi owo otun re ko nnkan ri. Bi bee ko nigba naa, ki awon opuro seyemeji (si al-Ƙur’an)

[49] Rara (ko ri bi won se ro o. al-Ƙur’an), ohun ni awon ayah t’o yanju ninu igba-aya awon ti A fun ni imo-esin. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alabosi

[50] Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so awon ami (iyanu) kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa lodo Re. Ati pe olukilo ponnbele ni emi.”

[51] Se ko to fun won (ni ami iyanu) pe A so tira (al-Ƙur’an) kale fun o, ti won n ke e fun won? Dajudaju ike ati isiti wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo

[52] So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin. O mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Awon t’o gba iro gbo, ti won si sai gbagbo ninu Allahu; awon wonyen, awon ni eni ofo

[53] Won si n kan o loju nipa iya! Ti ko ba je pe o ti ni gbedeke akoko kan ni, iya naa iba kuku de ba won. (Iya) iba de ba won ni ojiji se, won ko si nii fura

[54] Won n kan o loju nipa iya! Dajudaju ina Jahanamo kuku maa yi awon alaigbagbo po

[55] (Ranti) ojo ti iya yoo bo won mole lati oke won ati isale ese won, (Allahu) si maa so pe: “E to (iya) ohun ti e n se nise wo.”

[56] Eyin erusin Mi, ti e gbagbo ni ododo, dajudaju ile Mi gbooro. Nitori naa, Emi nikan ni ki e josin fun

[57] Gbogbo emi l’o maa to iku wo. Leyin naa, odo Wa ni won yoo da yin pada si

[58] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon ile peteesi giga kan ninu Ogba Idera, ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Esan awon oluse-rere si dara

[59] (Awon ni) awon t’o se suuru. Oluwa won si ni won n gbarale

[60] Meloo meloo ninu awon eranko ti ko le da bukata ije-imu re gbe, ti Allahu si n se ije-imu fun awon ati eyin. Oun si ni Olugbo, Onimo

[61] Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile, ti O si ro oorun ati osupa?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” Nitori naa, bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo

[62] Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. O si n diwon re fun elomiiran. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[63] Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O so omi kale lati sanmo, ti O fi ta ile ji leyin ti o ti ku?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ni ko se laakaye.”

[64] Ki ni isemi aye yii bi ko se iranu ati ere sise. Ati pe dajudaju Ile Ikeyin si ni isemi gbere ti won ba mo

[65] Nigba ti won ba gun oko oju-omi, won yoo pe Allahu (gege bi) olusafomo-adua fun Un. Amo nigba ti O ba ko won yo si ori ile, nigba naa ni won yoo maa sebo

[66] nitori ki won le sai moore si nnkan ti A fun won ati nitori ki won le jayekaye. Nitori naa, laipe won maa mo

[67] Se won ko ri i pe dajudaju Awa se Haram (Mokkah) ni aye ifayabale, ti won si n ji awon eniyan gbe lo ni ayika won? Se iro ni won yoo gbagbo, ti won yo si sai moore si idera Allahu

[68] Ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu, tabi t’o pe ododo ni iro nigba ti o de ba a? Se inu ina Jahanamo ko ni ibugbe fun awon alaigbagbo ni

[69] Awon t’o gbiyanju nipa Wa, dajudaju A maa fi won mo awon ona Wa. Ati pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluse-rere

Àwọn ará Róòmù

Surah 30

[1] ’Alif lam mim

[2] Won segun Romu

[3] ni awon ile t’o wa nitosi (erekusu Larubawa). Leyin isegun won, awon naa maa segun won

[4] ni odun mewaa (si igba naa). Ti Allahu ni ase ni isaaju ati ni ikeyin. Ni ojo yen, awon onigbagbo ododo maa dunnu

[5] si aranse Allahu. O n saranse fun eni ti O ba fe. Oun si ni Alagbara, Asake-orun

[6] (Eyi je) adehun Allahu. Allahu ko si nii yapa adehun Re, sugbon opolopo awon eniyan ko mo

[7] Won nimo nipa gbangba ninu oro isemi aye (yii). Afonu-fora si ni won nipa Ojo Ikeyin

[8] Se won ko ronu nipa oro ara won ni? Allahu ko seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin awon mejeeji bi ko se pelu ododo ati fun gbedeke akoko kan. Dajudaju opolopo ninu awon eniyan ma ni alaigbagbo ninu ipade Oluwa won

[9] Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won ni agbara ju won lo. Won fi ile dako. Won si lo ile fun ohun ti o po ju bi (awon ara Mokkah) se lo o. Awon Ojise won si mu awon eri t’o yanju wa ba won. Nitori naa, Allahu ko sabosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si

[10] Leyin naa, aburu je atubotan awon t’o saburu nitori pe won pe awon ayah Allahu niro. Won si n fi se yeye

[11] Allahu n pile eda dida. Leyin naa, O maa da a pada (sipo alaaye). Leyin naa, odo Re ni won yoo da yin pada si

[12] Ni ojo ti Akoko naa maa sele, awon elese yo soreti nu

[13] Ati pe ko nii si awon olusipe fun won ninu awon orisa won. Won si maa je alatako orisa won

[14] Ni ojo ti Akoko naa maa sele, ni ojo yen ni won yoo pinya si otooto

[15] Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, won yoo wa ni aye t’o rewa julo ninu Ogba Idera, ti won yo si maa dunnu

[16] Ni ti awon t’o sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa ati ipade Ojo Ikeyin niro, awon wonyen ni won yoo ko wa sinu Ina

[17] Nitori naa, e se afomo fun Allahu nigba ti e ba wa ni ale ati nigba ti e ba wa ni owuro

[18] TiRe si ni ope ninu awon sanmo ati lori ile ni asale ati nigba ti e ba wa ni osan

[19] (Allahu) n yo alaaye jade lati ara oku. O n yo oku jade lati ara alaaye. O n ta ile ji leyin ti ile ti ku. Bayen ni A oo se mu eyin naa jade

[20] O wa ninu awon ami Re pe, O seda yin lati ara erupe. Leyin naa, nigba naa eyin di abara ti e n fonka (lori ile aye)

[21] O wa ninu awon ami Re pe, O seda awon aya fun yin lati ara yin nitori ki e le ri ifayabale lodo won. O si fi ife ati ike si aarin yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o larojinle

[22] O wa ninu awon ami Re, dida awon sanmo ati ile ati okan-o-jokan awon ede yin ati awon awo ara yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon onimo

[23] Ninu awon ami Re ni oorun yin ni ale ati ni osan ati wiwa ti e n wa ninu oore Re (fun ije-imu). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro

[24] Ninu awon ami Re tun ni fifi monamona han yin ni ti eru ati ireti. O si n so omi kale lati sanmo. O n fi ta ile ji leyin ti ile ti ku. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n se laakaye

[25] Ati pe ninu awon ami Re ni pe sanmo ati ile duro pelu ase Re. Leyin naa, nigba ti O ba pe yin ni ipe kan nigba naa ni eyin yoo maa jade lati inu ile

[26] TiRe ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Eni kookan ni olutele-ase Re

[27] Oun ni Eni ti O n bere eda dida. Leyin naa, O maa da a pada (sipo alaaye fun ajinde). O si rorun julo fun Un (lati se bee). TiRe ni iroyin t’o ga julo ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon

[28] (Allahu) sakawe kan fun yin nipa ara yin. Nje e ni akegbe ninu awon eru yin lori ohun ti A fun yin ni arisiki, ti e jo maa pin (dukia naa) ni dogbadogba, ti e o si maa paya won gege bi won se n paya eyin naa? Bayen ni A se n s’alaye awon ayah fun ijo t’o n se laakaye

[29] Nse ni awon t’o sabosi tele ife-inu won lai si imo kan (fun won). Ta si ni o le fi ona mo eni ti Allahu ba si lona? Ko si nii si awon alaranse fun won

[30] Nitori naa, doju re ko esin naa, (ki o je) oluduro-deede-ninu-esin, esin adamo Allahu eyi ti O da mo awon eniyan. Ko si si iyipada fun eda Allahu. Iyen ni esin t’o feserinle, sugbon opolopo awon eniyan ko mo

[31] (E je) oluseri si odo Allahu (nipa ironupiwada). E paya Re. E kirun. E ma se wa ninu awon osebo

[32] (E ma se wa) ninu awon t’o da esin won si kelekele, ti won si di ijo-ijo. Ijo kookan si n yo si ohun ti o wa lodo won

[33] Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, won yoo pe Oluwa won, ti won yoo maa seri pada sodo Re. Leyin naa, nigba ti (Allahu) ba fun won ni ike kan to wo lati odo Re, nigba naa ni igun kan ninu won yoo maa sebo si Oluwa won

[34] nitori ki won le sai moore si ohun ti (Allahu) fun won. E maa jaye lo. Nitori naa, laipe e maa mo

[35] Tabi A so eri kan kale fun won, t’o n soro nipa nnkan ti won n so di akegbe Re

[36] Nigba ti A ba fi ike kan to eniyan lenu wo, won yoo dunnu si i. Ti aburu kan ba si kan won nipa ohun ti owo won ti siwaju, nigba naa ni won yoo soreti nu

[37] Se won ko ri i pe dajudaju Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe, (O si n) diwon re (fun eni ti O ba fe)? Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo

[38] Nitori naa, fun ebi ni eto re. (Fun) mekunnu ati onirin-ajo ti agara da (ni nnkan). Iyen loore julo fun awon t’o n fe Oju rere Allahu. Awon wonyen, awon si ni olujere

[39] Ohunkohun ti e ba fun (awon eniyan) ni ebun, nitori ki o le di ele lati ara dukia awon eniyan, ko le lekun ni odo Allahu. Ohunkohun ti e ba si (fun awon eniyan) ni Zakah, ti e n fe oju rere Allahu, awon wonyen ni A maa fun ni adipele esan

[40] Allahu, Eni ti O seda yin, leyin naa, O fun yin ni arisiki, leyin naa, O maa so yin di oku, leyin naa, O maa so yin di alaaye. Nje o wa ninu awon orisa yin eni ti o le se nnkan kan ninu iyen? Mimo ni fun Un. O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[41] Ibaje han lori ile ati loju omi nipase ohun ti owo awon eniyan se nise (aburu) nitori ki (Allahu) le fi (iya) apa kan eyi ti won se nise (aburu) to won lenu wo nitori ki won le seri pada (nibi aburu)

[42] So pe: “E rin lori ile, ki e wo bi atubotan awon t’o siwaju se ri! Opolopo won ni won je osebo.”

[43] Nitori naa, doju re ko esin t’o feserinle siwaju ki ojo kan to de, ti ko si nnkan ti o le ye e lodo Allahu. Ni ojo yen ni awon eniyan yoo pinya si (ero Ogba Idera ati ero Ina)

[44] Enikeni ti o ba sai gbagbo, ori ara re ni (iya) aigbagbo re wa. Enikeni ti o ba si se ise rere, emi ara won ni won n te ite (Ogba Idera) sile fun

[45] nitori ki (Allahu) le san esan rere ninu oore ajulo Re fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alaigbagbo

[46] Ninu awon ami Re ni pe, O n ran ategun ni iro idunnu. Ati pe nitori ki (Allahu) le fun yin to wo ninu ike Re; ati nitori ki oko oju-omi le rin loju-omi pelu ase Re; ati nitori ki e le wa ninu oore Re; ati nitori ki e le dupe

[47] Dajudaju A ti ran awon Ojise kan nise siwaju re si awon ijo won. Won si wa ba won pelu awon eri t’o yanju. A si gbesan lara awon t’o dese. O si je eto fun wa lati se aranse fun awon onigbagbo ododo

[48] Allahu ni Eni t’O n fi awon ategun ranse. (Ategun naa) si maa tu esujo soke. (Allahu) yo si te (esujo) sile s’oju sanmo bi O ba se fe. O si maa da a kelekele (si oju sanmo). O si maa ri ojo ti o ma maa jade laaarin re. Nigba ti O ba si ro (ojo naa) fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re, nigba naa won yo si maa dunnu

[49] Bi o tile je pe siwaju ki O to so o kale fun won, won ti soreti nu siwaju re

[50] Nitori naa, woye si awon oripa ike Allahu, (wo) bi (Allahu) se n ta ile ji leyin ti ile ti ku. Dajudaju (Allahu) yii ni O kuku maa so awon oku di alaaye. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[51] Dajudaju ti A ba ran ategun kan (si won), ki won si ri (nnkan ogbin won) ni pipon (jijona), dajudaju won yo si maa sai moore lo leyin re

[52] Dajudaju iwo ko l’o maa mu awon oku gboro. O o si nii mu awon aditi gbo ipe nigba ti won ba keyin si o, ti won n lo

[53] Iwo ko l’o maa fi ona mo awon afoju nibi isina won. Ko si eni ti o maa mu gbo oro afi eni ti o ba gba awon ayah Wa gbo. Awon si ni (musulumi) olujupa-juse-sile fun Allahu. Allahu (subhanahu wa ta'ala) l’O n sise iyanu. Ko si si Anabi tabi Ojise Olohun kan ti Allahu ko fun ni ise iyanu kan tabi omiran se ni ibamu si igba eni kookan won. Bee si ni eyikeyii ise iyanu ti o ba towo Anabi tabi Ojise kan waye ko so Anabi tabi Ojise naa di oluwa ati olugbala. Allahu nikan soso ni Oluwa ati Olugbala aye ati orun. Nitori naa fun alekun lori awon ise iyanu Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ti Allahu ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan. Amo awon kristieni gege bi isesi won bi o se n wu u to ati bi o se n jerankan to ni pe ki gbogbo awon eniyan re gbagbo ninu Allahu. Amo won ko gbagbo

[54] Allahu, Eni ti O seda yin lati (ara nnkan) lile, leyin naa, leyin lile O fun (yin ni) agbara, leyin naa, leyin agbara, O tun fi lile ati ogbo (si yin lara). O n da ohunkohun ti O ba fe. Oun si ni Onimo, Alagbara

[55] Ati pe ni ojo ti Akoko naa ba sele (iyen, ojo Ajinde), awon elese yoo maa bura pe awon ko gbe (ile aye) ju akoko kan lo.” Bayen ni won se maa n f’iro tanra won je

[56] Awon ti A fun ni imo ati igbagbo ododo yoo so pe: “Dajudaju ninu akosile ti Allahu, e ti gbe ile aye titi Ojo Ajinde (fi to). Nitori naa, eyi ni Ojo Ajinde, sugbon eyin ko mo.”

[57] Nitori naa ni ojo yen, awon t’o sabosi, awawi won ko nii se won ni anfaani. Won ko si nii fun won ni aye lati se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu

[58] A kuku ti fi orisirisi akawe lele ninu al-Ƙur’an yii fun awon eniyan. Dajudaju ti o ba mu ayah kan wa fun won, dajudaju awon t’o sai gbagbo yoo wi pe: “Eyin (musulumi) ko je kini kan tayo opuro.”

[59] Bayen ni Allahu se n fi edidi di okan awon ti ko nimo

[60] Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ma se je ki awon ti ko mo amodaju (nipa Ojo esan) so o dope

Luqmānì

Surah 31

[1] ’Alif lam mim

[2] Iwonyi ni awon ayah Tira ogbon

[3] (O je) imona ati ike fun awon oluse-rere

[4] awon t’o n kirun, ti won n yo zakah. Awon si ni won ni amodaju nipa Ojo Ikeyin

[5] Awon wonyen wa lori imona lati odo Oluwa won. Awon wonyen si ni awon olujere

[6] O wa ninu awon eniyan, eni t’o n ra iranu-oro lati fi si awon eniyan lona kuro loju ona (esin) Allahu pelu ainimo ati nitori ki o le so esin di yeye. Awon wonyen si ni iya ti i yepere eda wa fun

[7] Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa peyinda ni ti igberaga, afi bi eni pe ko gbo o, afi bi eni pe edidi wa ninu eti re mejeeji. Nitori naa, fun un ni iro iya eleta-elero

[8] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, awon Ogba Idera n be fun won

[9] Olusegbere ni won ninu re. (O je) adehun ti Allahu se ni ti ododo. Oun si ni Alagbara, Ologbon

[10] O da awon sanmo lai ni opo ti e le ri. O si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu ile ki o ma fi le mi mo yin lese. O fon gbogbo nnkan abemi ka sori ile. A tun so omi kale lati sanmo, A si fi mu gbogbo orisirisi eso daadaa hu jade lati inu ile

[11] Eyi ni eda ti Allahu. Nitori naa, e fi ohun ti awon miiran leyin Re da han mi! Rara o! Awon alabosi wa ninu isina ponnbele ni

[12] Dajudaju A ti fun Luƙmon ni ogbon, pe: “Dupe fun Allahu.” Enikeni ti o ba dupe, o n dupe fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si sai moore, dajudaju Allahu ni Oloro, Olope (ti ope to si)

[13] (Ranti) nigba ti Luƙmon so fun omo re nigba ti o n se waasi fun un, pe: “Omo mi, ma se sebo si Allahu. Dajudaju ebo sise ni abosi nla

[14] Ati pe A pa a ni ase fun eniyan nipa awon obi re mejeeji - iya re gbe e ka (ninu oyun) pelu ailera lori ailera, o si gba omu lenu re laaarin odun meji – (A so) pe: “Dupe fun Emi ati awon obi re mejeeji.” Odo Mi si ni abo eda

[15] Ti awon mejeeji ba si ja o logun pe ki o fi ohun ti iwo ko ni imo nipa re sebo si Mi, ma se tele awon mejeeji.1 Fi daadaa ba awon mejeeji lo po ni ile aye.2 Ki o si tele oju ona eni ti o ba seri pada si odo Mi (ni ti ironupiwada). Leyin naa, odo Mi ni ibupadasi yin. Nitori naa, Mo maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise. nnkan daadaa ni. Iketa: ohunkohun ti asa ati ise eya eda kookan ba pe ni daadaa nnkan daadaa ni ni odiwon igba ti ayah kan tabi hadith kan ko ba ti lodi si irufe nnkan naa. Bi apeere

[16] Omo mi, dajudaju ti o ba je pe odiwon eso kardal kan lo wa ninu apata, tabi ninu awon sanmo, tabi ninu ile, Allahu yoo mu un wa. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Alamotan

[17] Omo mi, kirun, p’ase rere, ko aburu, ki o si se suuru lori ohun ti o ba sele si o. Dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan

[18] Ma se ko parike re si eniyan. Ma si se rin lori ile pelu faari. Dajudaju Allahu ko feran gbogbo onigbeeraga, onifaari

[19] Je ki irin ese re wa ni iwontun-wonsi, ki o si re ohun re nile. Dajudaju ohun t’o buru julo ma ni ohun ketekete.”

[20] Se e o ri i pe dajudaju Allahu ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile fun yin, O si pe awon ike Re fun yin ni gbangba ati ni koro? O si wa ninu awon eniyan eni t’o n jiyan nipa Allahu lai ni imo (al-Ƙur’an) ati imona (ninu sunnah Anabi s.a.w.) ati tira (onimo-esin) t’o n tan imole (si oro esin)

[21] Nigba ti won ba si so fun won pe: “E tele ohun ti Allahu sokale.” Won a wi pe: “Rara! A maa tele ohun ti a ba lowo awon baba wa ni.” (Se won yoo tele awon baba won) t’ohun ti bi Esu se n pe won sibi iya Ina t’o n jo fofo

[22] Enikeni ti o ba jura re sile fun Allahu, ti o je oluse-rere, dajudaju onitoun ti diro mo okun t’o fokan bale julo. Ati pe odo Allahu ni ikangun awon oro (eda)

[23] Enikeni ti o ba si sai gbagbo, ma se je ki aigbagbo re ko ibanuje ba o. Odo Wa ni ibupadasi won. Nigba naa, A maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda

[24] A maa fun won ni igbadun die. Leyin naa, A maa taari won sinu iya t’o nipon

[25] Dajudaju ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ko mo

[26] Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope

[27] Ti o ba je pe kikida ohun t’o n be lori ile ni igi ni gege ikowe, ki agbami odo je tadaa re, agbami odo meje (tun wa) leyin re (t’o maa kun un), awon oro Allahu ko nii tan (leyin ti awon nnkan ikowe wonyi ba tan nile). Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon

[28] Iseda yin ati ajinde yin ko tayo bi (iseda ati ajinde) emi eyo kan. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran

[29] Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O n ti oru bo inu osan, O n ti osan bo inu oru, O si ro oorun ati osupa? Ikookan won si n rin titi di gbedeke akoko kan. Ati pe (se o o ri i pe) dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[30] Iyen nitori pe, dajudaju Allahu, Oun ni Ododo. Ati pe dajudaju ohun ti won n pe leyin Re ni iro. Dajudaju Allahu, O ga, O tobi

[31] Se o o ri i pe dajudaju oko oju-omi n rin ni oju omi pelu idera Re, (sebi) nitori ki (Allahu) le fi han yin ninu awon ami Re ni? Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe

[32] Nigba ti igbi omi ba bo won mole daru bi awon apata ati esujo, won a pe Allahu (gege bi) olusafomo-adua fun Un. Nigba ti O ba si gba won la sori ile, onideede si maa wa ninu won. Ko si si eni t’o maa tako awon ayah Wa afi gbogbo odale, alaimoore

[33] Eyin eniyan, e beru Oluwa yin. Ki e si paya ojo kan ti obi kan ko nii sanfaani fun omo re; ati pe omo kan, oun naa ko nii sanfaani kini kan fun obi re. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Nitori naa, isemi aye yii ko gbodo tan yin je. (Esu) eletan ko si gbodo tan yin je nipa Allahu

[34] Dajudaju Allahu, odo Re ni imo Akoko naa wa. O n so ojo kale. O mo ohun t’o wa ninu apoluke. Emi kan ko si mo ohun ti o maa se nise ni ola. Emi kan ko si mo ile wo l’o maa ku si. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alamotan

Ìforíbalẹ̀

Surah 32

[1] ’Alif lam mim

[2] Isokale Tira naa, ko si iyemeji ninu re (pe o wa) lati odo Oluwa gbogbo eda

[3] Tabi won n wi pe: “O da adapa iro re ni.” Rara o! Ododo ni lati odo Oluwa re nitori ki o le fi sekilo fun awon eniyan kan, ti olukilo kan ko wa ba won ri siwaju re, nitori ki won le mona

[4] Allahu ni Eni ti O seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin mejeeji laaarin ojo mefa. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. Ko si alaabo ati olusipe kan fun yin leyin Re. Se e o nii lo iranti ni

[5] O n seto oro (eda) lati sanmo wa sori ile. Leyin naa, (abo oro eda) yoo gunke to O lo laaarin ojo kan ti odiwon re to egberun odun ninu onka ti e n ka

[6] Iyen ni Onimo-ikoko ati gbangba, Alagbara, Asake-orun

[7] Eni t’o se gbogbo nnkan ti O da ni daadaa. O si bere iseda eniyan lati inu erupe amo

[8] Leyin naa, O se awon aromodomo re lati ara ohun ti A mu jade lati ara omi lile yepere

[9] Leyin naa, O to (orikeerikee) re dogba. O si fe (emi) si i lara ninu emi Re (ti O da). O tun se igboro, iriran ati okan fun yin. Die ni ope ti e n da

[10] Won si wi pe: “Nje nigba ti a ba ti poora sinu ile, nje awa tun le wa ni eda titun mo? Ani se, awon ni alaigbagbo ninu ipade Oluwa won

[11] So pe: “Molaika iku eyi ti A fi ti yin maa gba emi yin. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won maa da yin pada si.” gege bi O se je Eledaa ohun gbogbo. Ko si eda kan ti o maa to isemi wo afi pelu iyonda Allahu (subhanahu wa ta'ala). Ko si si eda kan ti o maa to iku wo afi pelu iyonda Allahu (subhanahu wa ta'ala). Nipa eyi Allahu l’O n fi ase Re gba emi kuro lara eda Re ni akoko ti O ti ko mo on ninu kadara. Iyen ni o jeyo ninu surah az-Zumor; 39:42. Bakan naa

[12] (Iwo iba ri eemo) ti o ba je pe o ri awon elese nigba ti won ba sori ko ni odo Oluwa won, (won si maa wi pe): “Oluwa wa, a ti riran, a si ti gboran (bayii), nitori naa, da wa pada (si ile aye) nitori ki a le lo se ise rere; dajudaju awa ni alamodaju.”

[13] Ti o ba je pe A ba fe ni, dajudaju A iba fun gbogbo emi kookan ni imona re, sugbon oro naa ti se lati odo Mi (bayii pe): “Dajudaju Mo maa mu ninu awon alujannu ati eniyan ni apapo kun inu ina Jahanamo.”

[14] Nitori naa, e to iya wo nitori pe e ti gbagbe ipade ojo yin (oni) yii. Dajudaju Awa naa yoo gbagbe yin sinu Ina. E to iya gbere wo nitori ohun ti e n se nise

[15] Awon t’o gbagbo ninu awon ayah Wa ni awon ti o je pe nigba ti won ba fi se isiti fun won, won yoo doju bole ni oluforikanle, won yo si se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won ko si nii segberaga

[16] Won n gbe egbe won kuro lori ibusun. Won si n pe Oluwa won ni ti ipaya ati ireti. Won si n na ninu ohun ti A pese fun won

[17] Ko si emi kan ti o mo ohun ti A fi pamo fun won ninu awon nnkan itutu oju. (O je) esan ohun ti won n se nise (rere)

[18] Nje eni t’o je onigbagbo ododo da bi eni t’o je obileje bi? Won ko dogba

[19] Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, awon ibugbe (ninu) Ogba Idera n be fun won. (O je) ohun ti A pese sile (de won) nitori ohun ti won n se nise (rere)

[20] Ni ti awon t’o baleje, Ina ni ibugbe won. Igbakigba ti won ba fe jade kuro ninu re, A o si maa da won pada sinu re. A si maa so fun won pe: “E to iya Ina ti e n pe niro wo.”

[21] Dajudaju A maa fun won to wo ninu iya t’o kere julo (nile aye) yato si iya t’o tobi julo (lorun) nitori ki won le seri pada (sibi ododo siwaju iku won)

[22] Ati pe ta l’o se abosi t’o tayo eni ti won fi awon ayah Wa se isiti fun, leyin naa, ti o gbunri kuro nibe? Dajudaju Awa maa gbesan lara awon elese

[23] Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira. Nitori naa, ma se wa ninu iyemeji nipa bi o se pade re (iyen, ninu irin-ajo oru ati gigun sanmo). A si se Tira naa ni imona fun awon omo ’Isro’il

[24] Ati pe A se awon asiwaju kan ninu won ni afinimona pelu ase Wa nigba ti won se suuru. Won si n ni amodaju nipa awon ayah Wa

[25] Dajudaju Oluwa re, O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si

[26] Se ko foju han si won pe, meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Awon naa si n rin koja ninu awon ibugbe won! Dajudaju awon ami wa ninu iyen. Nitori naa, se won ko nii teti gboro (ododo ni)

[27] Tabi won ko ri i pe dajudaju Awa l’A n wa omi ojo lo sori ile gbigbe, ti A si n fi mu irugbin jade? Awon eran-osin won ati awon naa si n je ninu re. Nitori naa, se won ko riran ni

[28] Won si n wi pe: “Igba wo ni Idajo yii ti e ba je olododo?”

[29] So pe: “Ni Ojo Idajo, igbagbo won ko nii sanfaani fun awon t’o sai gbagbo (ninu Allahu). A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina).”

[30] Nitori naa, seri kuro lodo won, ki o si maa reti (Ojo Idajo). Dajudaju awon naa n reti (re)

Àwọn ẹgbẹ́

Surah 33

[1] Iwo Anabi, beru Allahu. Ma si tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon

[2] Tele ohun ti A n mu wa fun o ni imisi lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[3] Ki o si gbarale Allahu. Allahu si to ni Oluso

[4] Allahu ko fun eniyan kan ni okan meji ninu ikun re. (Allahu) ko si so awon iyawo yin, ti e n fi eyin won we eyin iya yin, di iya yin. Ati pe (Allahu) ko so awon omo-olomo ti e n pe ni omo yin di omo yin. Iyen ni oro enu yin. Allahu n so ododo. Ati pe Oun l’O n fi (eda) mona

[5] E pe won pelu oruko baba won. Ohun l’o se deede julo lodo Allahu, sugbon ti e o ba mo (oruko) baba won, omo iya yin ninu esin ati eru yin kuku ni won. Ko si ese fun yin nipa ohun ti e ba sasise re, sugbon (ese wa nibi) ohun ti okan yin moomo se. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

[6] Anabi ni eto si awon onigbagbo ododo ju emi ara won lo (nipa ife re ati idajo re). Awon aya re si ni iya won. Ninu Tira Allahu, awon ebi, apa kan won ni eto si ogun jije ju apa kan lo. (Awon ebi tun ni eto si ogun jije) ju awon onigbagbo ododo ati awon t’o kuro ninu ilu Mokkah fun aabo esin, afi ti e ba maa se daadaa kan si awon ore yin (wonyi ni ogun le fi kan won pelu asoole). Iyen wa ninu Tira (Laohul-Mahfuth) ni akosile

[7] (Ranti) nigba ti A gba adehun ni owo awon Anabi ati ni owo re, ati ni owo (Anabi) Nuh, ’Ibrohim, Musa ati ‘Isa omo Moryam. A gba adehun ni owo won ni adehun t’o nipon

[8] nitori ki (Allahu) le beere (ododo) awon olododo nipa ododo won. O si pese iya eleta-elero sile de awon alaigbagbo

[9] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti idera Allahu lori yin, nigba ti awon omo ogun (onijo) de ba yin. A si ran ategun ati awon omo ogun ti e o foju ri si won. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se

[10] (E ranti) nigba ti won de ba yin lati oke yin ati isale yin, ati nigba ti awon oju ye (sotun-un sosi), ti awon okan si de ona-ofun (ni ti ipaya). E si n ro awon ero kan nipa Allahu

[11] Nibe yen ni won ti fi adanwo kan awon onigbagbo ododo. Won si mile mo won lese ni imititi lile

[12] (E ranti) nigba ti awon sobe-selu musulumi ati awon ti aisan wa ninu okan won n wi pe: “Allahu ati Ojise Re ko se adehun kan fun wa bi ko se etan.”

[13] (E ranti) nigba ti igun kan ninu won wi pe: “Eyin ara Yethrib, ko si aye (isegun) fun yin, nitori naa, e seri pada (lodo Ojise).” Apa kan ninu won si n toro iyonda lowo Anabi, won n wi pe: “Dajudaju ile wa da paroparo ni.” (Ile won) ko si da paroparo. Won ko si gbero ohun kan tayo sisagun

[14] Ati pe ti o ba je pe (omo ogun onijo) wole to won wa lati awon iloro ilu (Modinah), leyin naa, ki won pe (awon sobe-selu musulumi) sinu ebo sise, won iba sebo. Won ko si nii gbe ninu ilu mo tayo igba die (ti won yoo fi pare)

[15] Dajudaju won ti ba Allahu se adehun siwaju pe awon ko nii peyinda (lati sagun). Adehun Allahu si je ohun ti won maa beere (lowo won)

[16] So pe: “Sisagun yin ko le se yin ni anfaani, ti e ba sa fun iku tabi pipa (si oju ogun esin. Ti e ba si sagun) nigba naa, A o nii fun yin ni igbadun aye bi ko se fun igba die

[17] So pe: “Ta ni eni ti o le da aabo bo yin lodo Allahu ti O ba fe fi aburu kan yin tabi ti O ba fe ke yin?” Won ko si le ri alaabo tabi alaranse kan leyin Allahu

[18] Dajudaju Allahu ti mo awon t’o n fa eniyan seyin ninu yin ati awon t’o n wi fun awon arakunrin won pe: “E maa bo wa si odo wa.” Won ko si nii lo si oju ogun esin afi (ogun) die

[19] Won ni ahun si yin (lati se iranlowo). Nigba ti iberu (ogun) ba de, o maa ri won ti won yoo maa wo o. Oju won yo si maa yi kiri rakorako (ni ti iberu) bi eni ti o fe daku, sugbon nigba ti iberu (ogun) ba lo, (ti ikogun ba de), won yoo maa fi awon ahon kan t’o mu berebere ba yin soro ni ti sise okanjua si oore naa. Awon wonyen ko gbagbo ni ododo. Nitori naa, Allahu ba awon ise won je. Iyen si n je irorun fun Allahu

[20] Won n lero pe awon omo ogun onijo ko ti i lo, (won si ti tuka). Ti awon omo ogun onijo ba (si pada) de, dajudaju (awon sobe-selu musulumi) yoo fe ki awon ti wa ni oko laaarin awon Larubawa oko, ki won maa beere nipa awon iro yin (pe se e ti ku tan tabi e si wa laye). Ti o ba si je pe won wa laaarin yin, won ko nii jagun bi ko se fun igba die

[21] Dajudaju awokose rere wa fun yin lara Ojise Allahu fun enikeni ti o ba n reti (esan) Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si ranti Allahu ni opolopo (igba)

[22] Nigba ti awon onigbagbo ododo ri awon omo ogun onijo, won so pe: “Eyi ni ohun ti Allahu ati Ojise Re se ni adehun fun wa. Allahu ati Ojise Re ti so ododo oro.” (Riri won) ko se alekun kan fun won bi ko se (alekun) igbagbo ododo ati ijuwo-juse-sile (fun ase Allahu)

[23] O wa ninu awon onigbagbo ododo, awon okunrin kan ti won je olododo nipa adehun ti won ba Allahu se; o wa ninu won eni ti o pe adehun re (t’o si ku soju ogun esin), o si wa ninu won eni t’o n reti (iku tire). Won ko si yi (adehun) pada rara

[24] (Iwonyi ri bee) nitori ki Allahu le fi (ododo) awon olododo san won ni esan ododo won, ati nitori ki O le je awon sobe-selu musulumi ni iya ti O ba fe tabi nitori ki O le gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu, O n je Alaforijin, Asake-orun

[25] Allahu si da awon t’o sai gbagbo pada tohun ti ibinu won; owo won ko si te oore kan. Allahu si to awon onigbagbo ododo nibi ogun naa. Allahu si n je Alagbara, Olubori

[26] (Allahu) si mu awon t’o seranlowo fun (awon omo ogun onijo) ninu awon ahlul-kitab sokale kuro ninu awon odi won. O si ju eru sinu okan won. E n pa igun kan (ninu won), e si n ko igun kan leru

[27] (Allahu) si jogun ile won, ile won, dukia won ati ile ti e o te ri fun yin. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan

[28] Iwo Anabi, so fun awon iyawo re pe: “Ti e ba fe isemi aye yii ati oso re, e wa nibi ki ng fun yin ni ebun ikosile, ki ng si fi yin sile ni ifisile t’o rewa

[29] Ti e ba si fe ti Allahu ati ti Ojise Re ati ile Ikeyin, dajudaju Allahu ti pese esan nla sile de awon oluse-rere lobinrin ninu yin.”

[30] Eyin iyawo Anabi, enikeni ninu yin ti o ba se ibaje t’o foju han, A maa di adipele iya ilopo meji fun un. Iyen si n je irorun fun Allahu

[31] Enikeni ti o ba n tele ti Allahu ati ti Ojise Re ninu yin, ti o si n se ise rere, A maa fun un ni esan ilopo meji. A si ti pese ije-imu alapon-onle sile de e.”

[32] Eyin iyawo Anabi, e o da bi eni kan kan ninu awon obinrin, ti e ba ti beru (Allahu). E ma se dinhun (si awon okunrin leti) nitori ki eni ti arun wa ninu okan re ma baa jerankan. Ki e si maa so oro t’o dara

[33] E fidi mole yin. E ma se fi ara ati oso han nita gege bi ti ifara-foso-han igba aimokan akoko (iyen, siwaju ki e t’o di musulumi). E kirun. E yo Zakah. Ki e si tele (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re. Allahu kan n gbero lati mu egbin kuro lara yin, eyin ara ile (Anabi). Ati pe O (kan n gbero lati) fo yin mo tonitoni ni

[34] E ranti ohun ti won n ke ninu ile yin ninu awon ayah Allahu ati ijinle oye (iyen, sunnah Anabi). Dajudaju Allahu n je Alaaanu, Onimo-ikoko. ti Larubawa ba n d’oju oro ko okunrin tabi nnkan ako tabi o n soro nipa okunrin tabi nnkan ako ede Larubawa ti ni ihun ako fun ako. Bakan naa

[35] Dajudaju awon musulumi lokunrin ati musulumi lobinrin, awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, awon olutele-ase Allahu lokunrin ati awon olutele-ase Allahu lobinrin, awon olododo lokunrin ati awon olododo lobinrin, awon onisuuru lokunrin ati awon onisuuru lobinrin, awon olupaya Allahu lokunrin ati awon olupaya Allahu lobinrin, awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, awon alaawe lokunrin ati awon alaawe lobinrin, awon t’o n so abe won lokunrin ati awon t’o n so abe won lobinrin, awon oluranti Allahu ni opolopo lokunrin ati awon oluranti Allahu (ni opolopo) lobinrin; Allahu ti pese aforijin ati esan nla sile de won

[36] Ko to fun onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, nigba ti Allahu ati Ojise Re ba ti pari oro kan, lati ni esa (oro miiran) fun oro ara won. Ati pe enikeni ti o ba yapa (ase) Allahu ati (ase) Ojise Re, dajudaju o ti sina ni isina ponnbele

[37] (Ranti) nigba ti o n so fun eni ti Allahu sedera fun, ti iwo naa sedera fun1 pe: “Mu iyawo re dani, ki o si beru Allahu.” O si n fi pamo sinu emi re ohun ti Allahu yo safi han re. Ati pe o n paya awon eniyan. Allahu l’O si letoo julo pe ki o paya Re. Nigba ti Zaed ti pari bukata re lodo re (ti o si ti ko o sile), A ti se e ni iyawo fun o nitori ki o ma baa je laifi fun awon onigbagbo ododo lati fe iyawo omo-olomo ti won n pe ni omo won nigba ti won ba ti pari bukata won lodo won (ti won si ti ko won sile). Ase Allahu si gbodo se

[38] Ko si laifi fun Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) nipa ohun ti Allahu se ni eto fun un. (O je) ilana Allahu lori awon t’o ti lo siwaju. Ati pe ase Allahu je akoole kan t’o gbodo se

[39] (Kose awon t’o ti lo siwaju ninu awon Ojise) awon t’o n je ise Allahu, ti won n paya Re, ti won ko si paya eni kan ayafi Allahu. Allahu si to ni Olusiro

[40] (Anabi) Muhammad ki i se baba eni kan kan ninu awon okunrin yin, sugbon (o je) Ojise Allahu ati opin awon Anabi. Allahu si n je Onimo nipa gbogbo nnkan. opuro asookun sesin wule ni oun. Iro enu re ti po ju. Alagbari ponnbele si ni pelu. Iru ise aburu ti seeu Ahmada Tijani se fun ’Islam gele naa ni mirza ghulam Ahmad se. Awon mejeeji ni Poolu laaarin awa musulumi. E wo die ninu iro nla re. Mirza ghulam Ahmad so pe: ""Allahu so fun mi ni ede Larubawa pe bi omo Mi lo se wa si Mi."" (Tadhkirah “Ti o ba je pe Anabi Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) ni opin awon Anabi Olohun ko ye fun Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) lati pada wa saye mo lopin aye.” Won tun so pe Anabi Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) ni opin awon Anabi Olohun amo isoro tiwon ni pe

[41] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti Allahu ni iranti pupo

[42] E safomo fun Allahu ni aaro ati ni irole

[43] (Allahu) Oun ni Eni t’O n ke yin, awon molaika Re (si n toro aforijin fun yin), nitori ki Allahu le mu yin kuro lati inu awon okunkun wa sinu imole. Ati pe O n je Asake-orun fun awon onigbagbo ododo

[44] Ikini won ni ojo ti won yoo pade Re ni "alaafia." O si ti pese esan alapon-onle sile de won

[45] Iwo Anabi, dajudaju Awa ran o nise (pe ki o je) olujerii, oniroo-idunnu, olukilo

[46] olupepe si odo Allahu pelu iyonda Re ati atupa imole

[47] Fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu pe dajudaju oore ajulo nla wa fun won lodo Allahu

[48] Ma se tele awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Fi bi won se n ko inira ba o sile. Ki o si gbarale Allahu. Allahu si n to ni Alamojuuto

[49] Eyin ti e gbagbo ni ododo lokunrin, nigba ti e ba fe awon onigbagbo ododo lobinrin, leyin naa ti e ko won sile siwaju ki e to ba won ni asepo loko-laya, ko si opo sise kan ti won yoo se fun yin. Nitori naa, e fun won ni ebun ikosile. Ki e si fi won sile ni ifisile t’o rewa

[50] Iwo Anabi, dajudaju Awa se e ni eto fun o awon iyawo re, ti o fun ni owo-ori won, ati awon eru ninu awon ti Allahu fi se ikogun fun o ati awon omobinrin arakunrin baba re ati awon omobinrin arabinrin baba re, ati awon omobinrin arakunrin iya re, ati awon omobinrin arabinrin iya re, awon t’o fi ilu Mokkah sile wa si ilu Modinah pelu re, ati onigbagbo ododo lobinrin, ti o ba fi ara re tore fun Anabi, ti Anabi naa si fe fi se iyawo. Iwo nikan ni (eyi) wa fun, ko si fun awon onigbagbo ododo lokunrin. A ti mo ohun ti A se ni oran-anyan fun won nipa awon iyawo won ati awon eru won. (Eyi ri bee) nitori ki o ma baa si laifi fun o. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

[51] Lora lati sunmo eni ti o ba fe ninu won. Fa eni ti o ba fe mora. Ati pe eni keni ti o ba tun wa (lati sunmo) ninu awon ti o o pin oorun fun, ko si ese fun o (lati se bee). Iyen sunmo julo lati mu oju won tutu idunnu. Won ko si nii banuje. Gbogbo won yo si yonu si ohunkohun ti o ba fun won. Allahu mo ohun ti n be ninu okan yin. Allahu si n je Onimo, Alafarada

[52] Ko letoo fun o (lati fe) awon obinrin (miiran) leyin (isori awon ti A se ni eto fun o, ko si letoo fun o) lati fi awon obinrin (miiran) paaro won, koda ki daadaa won jo o loju, afi awon eru re (nikan l’o le ko sile ninu awon iyawo re). Allahu si n je Oluso lori gbogbo nnkan

[53] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se wo awon inu ile Anabi afi ti won ba yonda fun yin lati wole jeun lai nii je eni ti yoo maa reti ki ounje jinna, sugbon ti won ba pe yin (fun ounje) e wo inu ile nigba naa. Nigba ti e ba si jeun tan, e tuka, e ma se jokoo kale tira yin fun oro kan mo (ninu ile re). Dajudaju iyen n ko inira ba Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam). O si n tiju yin. Allahu ko si nii tiju nibi ododo. Nigba ti e ba si fe beere nnkan ni odo awon iyawo re, e beere re ni odo won ni eyin gaga. Iyen je afomo julo fun okan yin ati okan won. Ko to fun yin lati ko inira ba Ojise Allahu. (Ko si to fun yin) lati fe awon iyawo re leyin (iku) re laelae. Dajudaju iyen je nnkan nla ni odo Allahu

[54] Ti e ba safi han kini kan tabi e fi pamo, dajudaju Allahu n je Onimo nipa gbogbo nnkan

[55] Ko si ese fun awon iyawo Anabi nipa awon baba won ati awon omokunrin won ati awon arakunrin won ati awon omokunrin arakunrin won ati awon omokunrin arabinrin won ati awon obinrin (egbe) won ati awon erukunrin won (lati wole ti won.) E beru Allahu. Dajudaju Allahu n je Arinu-rode gbogbo nnkan

[56] Dajudaju Allahu ati awon molaika Re n ke Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam). Eyin ti e gbagbo ni ododo, e toro ike fun un, ki e si ki i ni kiki alaafia. awon Sohabah naa (r.ahm) maa n se bee. Eyin naa e wo bi awon aafa sunnah se n se asolatu fun Anabi ninu awon oro isaaju ninu awon tira won. Ko si aburu ninu eyi rara. Sugbon musulumi yoo se agbekale ihun asolatu daran ti o ba fi le ko sinu okan ninu awon nnkan mefa kan. Ikini: Lilo awon oro ti o lodi si ofin ati adisokan ’Islam ninu awon gbolohun asolatu naa. Ikeji: Siso gbolohun asolatu yen gan-angan di ilana ti won yoo maa pepe si ti irufe gbolohun naa yoo fi wa da bi eni pe hadith kan l’o gba a wa

[57] Dajudaju awon t’o n fi inira kan Allahu ati Ojise Re, Allahu ti sebi le won nile aye ati ni orun. O si ti pese iya t’o n yepere eda sile de won

[58] Awon t’o n fi inira kan awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin nipa nnkan ti won ko se, dajudaju won ti ru eru (oran) iparomoni ati ese ponnbele

[59] Iwo Anabi so fun awon iyawo re, awon omobinrin re ati awon obinrin onigbagbo ododo pe ki won maa gbe awon aso jilbab won wo si ara won bamubamu. Iyen sunmo julo lati fi mo won (ni oluberu Allahu). Nipa bee, won ko nii fi inira kan won. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

[60] Ti awon sobe-selu musulumi, ati awon ti aisan n be ninu okan won ati awon tuletule ninu ilu Modinah ko ba jawo (nibi aburu), dajudaju A maa de o si won, (o si maa bori won). Leyin naa, won ko si nii ba o gbe adugbo po mo afi fun igba die

[61] Won di eni-isebile nibikibi ti owo ba ti ba won; won maa mu won, won si maa pa won taara

[62] (O je) ise Allahu lori awon t’o ti lo siwaju. O o si nii ri iyipada kan fun ise Allahu

[63] Awon eniyan n bi o leere nipa Akoko naa. So pe: “Odo Allahu nikan soso ni imo nipa re wa. Ati pe ki l’o maa fi mo o pe o see se ki Akoko naa ti sunmo!”

[64] Dajudaju Allahu sebi le awon alaigbagbo. O si pese Ina t’o n jo fofo sile de won

[65] Olusegbere ni won ninu re titi laelae; won ko nii ri oluso tabi alaranse kan

[66] Ni ojo ti A oo yi oju won pada ninu Ina, won yo si wi pe: “Yee! Awa iba tele ti Allahu, awa iba si tele ti Ojise.”

[67] Won wi pe: “Oluwa wa! Dajudaju awa tele awon asiwaju wa ati awon agbaagba wa. Won si si wa lona

[68] Oluwa wa! Fun won ni ilopo meji ninu iya. Ki O si sebi le won ni isebi t’o tobi.”

[69] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se da bi awon t’o fi inira kan (Anabi) Musa. Allahu si safomo re ninu ohun ti won wi. O si je eni abiyi lodo Allahu

[70] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu. Ki e si so oro ododo

[71] (Allahu) maa satunse awon ise yin fun yin, O si maa saforijin awon ese yin fun yin. Ati pe eni ti o ba tele ti Allahu ati Ojise Re, o kuku ti jere ni erenje nla

[72] Dajudaju Awa fi ise laada lo awon sanmo ati ile ati apata. Won ko lati gbe e; won paya re. Eniyan si gbe e. Dajudaju (eniyan) je alabosi, alaimokan

[73] (Eniyan teri gba esin asegbalaada) nitori ki Allahu le fi iya je awon sobe-selu musulumi lokunrin, awon sobe-selu musulumi lobinrin, awon osebo lokunrin ati awon osebo lobinrin ati nitori ki Allahu le gba ironupiwada fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

Ṣébà

Surah 34

[1] Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n je tiRe. Ati pe tiRe ni gbogbo ope ni orun. Oun si ni Ologbon, Alamotan

[2] O mo ohunkohun t’o n wonu ile ati ohunkohun t’o n jade latinu re. (O mo) ohunkohun t’o n sokale latinu sanmo ati ohunkohun t’o n gunke lo sinu re. Oun si ni Asake-orun, Alaforijin

[3] Awon alaigbagbo wi pe: “Akoko naa ko nii de ba wa.” So pe: “Bee ko. Emi fi Oluwa mi bura. Dajudaju o maa de ba yin (lati odo) Onimo-ikoko (Eni ti) odiwon omo ina-igun ko pamo fun ninu sanmo ati ninu ile. (Ko si nnkan ti o) kere si iyen tabi ti o tobi (ju u lo) afi ki o wa ninu akosile t’o yanju.”

[4] (O maa sele) nitori ki Allahu le san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won tun se ise rere. Awon wonyen ni aforijin ati ese alapon-onle n be fun

[5] Ati pe awon t’o se ise buruku nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni iya eleta-elero t’o buru n be fun

[6] Awon ti A fun ni imo ri i pe eyi ti won sokale fun o lati odo Oluwa re, ohun ni ododo, ati pe o n se itosona si ona Alagbara, Eleyin

[7] Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Se ki a toka yin si okunrin kan ti o maa fun yin ni iro pe nigba ti won ba fon yin ka tan patapata (sinu erupe), pe dajudaju e maa pada wa ni eda titun

[8] Se o da adapa iro mo Allahu ni tabi alujannu n be lara re ni?” Rara o! Awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ti wa ninu iya ati isina t’o jinna

[9] Se won ko ri ohun t’o n be niwaju won ati ohun t’o n be leyin won ni sanmo ati ile? Ti A ba fe, Awa iba je ki ile ri mo won lese, tabi ki A ja apa kan sanmo lule le won lori mole. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun gbogbo erusin, oluronupiwada

[10] Dajudaju A ti fun (Anabi) Dawud ni oore ajulo lati odo Wa; Eyin apata, e se afomo pelu re. (A pe) awon eye naa (pe ki won se bee.) A si ro irin fun un

[11] (A so fun un) pe se awon ewu irin t’o maa bo ara, se oruka-orun fun ewu irin naa niwon-niwon. Ki e si se rere. Dajudaju Emi ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[12] Ati pe (A te) ategun lori ba fun (Anabi) Sulaemon, irin osu kan ni irin owuro re, irin osu kan si ni irin irole re . A si mu ki odo ide maa san ninu ile fun un. O si wa ninu awon alujannu, eyi t’o n sise (fun un) niwaju re pelu iyonda Oluwa re. Ati pe eni ti o ba gbunri kuro nibi ase Wa ninu won, A maa fun un ni iya ina t’o n jo fofo to wo

[13] Won n se ise ti o ba fe fun un nipa mimo awon ile t’o dara, awon ere, awo koto fife bi abata ati awon ikoko t’o ridii mule. Eyin eniyan (Anabi) Dawud, e sise idupe (fun Allahu). Die ninu awon erusin Mi si ni oludupe

[14] Nigba ti A pase pe ki iku pa (Anabi) Sulaemon, ko si ohun ti o mu awon alujannu mo pe o ti ku bi ko se kokoro inu ile kan ti o je opa re. Nigba ti o wo lule, o han kedere si awon alujannu pe ti o ba je pe awon ni imo ikoko ni, awon iba ti wa ninu (ise) iya t’o n yepere eda

[15] Dajudaju ami kan wa fun awon Saba’ ninu ibugbe won; (ohun ni) ogba oko meji t’o wa ni otun ati ni osi. “E je ninu arisiki Oluwa yin. Ki e si dupe fun Un.” Ilu t’o dara ni (ile Saba’. Allahu si ni) Oluwa Alaforijin

[16] Won gbunri (nibi esin). Nitori naa, A ran adagun odo ti won mo odi yika si won. A si paaro oko won mejeeji fun won pelu oko meji miiran ti o je oko eleso kikoro, oko igi elegun-un ati kini kan die ninu igi sidir

[17] Iyen ni A fi san won ni esan nitori pe won sai moore. Nje A maa san eni kan lesan iya bi ko se alaimoore

[18] A si fi awon ilu kan t’o han si aarin ilu ti A ran adagun odo si ati awon ilu ti A fi ibukun si. A si seto ibuso niwon-niwon fun irin-ajo sise sinu awon ilu naa. E rin lo sinu won ni oru ati ni oju ojo pelu ifayabale

[19] (Awon ara ilu Saba’) wi pe: “Oluwa wa, mu awon irin-ajo wa lati ilu kan si ilu miiran jinna sira won.” Won se abosi si emi ara won. A si so won di itan. A si fon won ka patapata. Dajudaju awon ami kan wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe

[20] Dajudaju ’Iblis ti so aba re di ododo le won lori. Won si tele e afi igun kan ninu awon onigbagbo ododo

[21] (’Iblis) ko si ni agbara kan lori won bi ko se pe ki A le safi han eni t’o gba Ojo Ikeyin gbo kuro lara eni t’o wa ninu iyemeji nipa re. Oluso si ni Oluwa re lori gbogbo nnkan

[22] So pe: “E pe awon ti e so pe (won je oluwa) leyin Allahu.” Won ko ni ikapa odiwon omo-ina igun ninu sanmo tabi ninu ile. Won ko si ni ipin kan ninu mejeeji. Ati pe ko si oluranlowo kan fun Allahu laaarin won

[23] Isipe ko si nii sanfaani lodo Allahu afi fun eni ti O ba yonda fun. (Inufu-ayafu ni awon olusipe ati awon olusipe-fun maa wa) titi A oo fi yo ijaya kuro ninu okan won. Won si maa so (fun awon molaika) pe: “Ki ni Oluwa yin so (ni esi isipe)?” Won maa so pe: “Ododo l’O so (isipe yin ti wole. Allahu) Oun l’O ga, O tobi

[24] So pe: “Ta ni O n pese fun yin lati inu awon sanmo ati ile?” So pe: “Allahu ni.” Dajudaju awa tabi eyin wa ninu imona tabi ninu isina ponnbele

[25] So pe: “Won ko nii bi yin leere nipa ese ti a da; won ko si nii bi awa naa nipa ohun ti e n se nise.”

[26] So pe: “Oluwa wa yoo ko wa jo papo. Leyin naa, O maa fi ododo sedajo laaarin wa. Oun si ni Onidaajo, Onimo.”

[27] So pe: “E fi han mi na awon orisa ti e dapo mo Allahu.” Rara (ko ni akegbe). Rara se, Oun ni Alagbara, Ologbon

[28] A o ran o nise afi si gbogbo eniyan patapata; (o je) oniroo-idunnu ati olukilo sugbon opolopo awon eniyan ko mo

[29] Won si n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo?”

[30] So pe: “Adehun ojo kan n be fun yin, ti eyin ko le sun siwaju di igba kan, e o si le fa a seyin.”

[31] Awon t’o sai gbagbo wi pe: “A o nii ni igbagbo ninu al-Ƙur’an yii ati eyi t’o wa siwaju re.” Ti o ba je pe o ba ri won ni nigba ti won ba da awon alabosi duro niwaju Oluwa won, (o maa ri won ti) apa kan won yoo da oro naa pada si apa kan; awon ti won so di ole (ninu won) yoo wi fun awon t’o segberaga (ninu won) pe: “Ti ki i ba se eyin ni, awa iba je onigbagbo ododo.”

[32] Awon t’o segberaga yo si wi fun awon ti won so di ole pe: “Se awa l’a se yin lori kuro ninu imona leyin ti o de ba yin? Rara o! Odaran ni yin ni.”

[33] Awon ti won so di ole yo si wi fun awon t’o segberaga pe: “Rara! Ete oru ati osan (lati odo yin loko ba wa) nigba ti e n pa wa ni ase pe ki a sai gbagbo ninu Allahu, ki a si so (awon kan) di egbe Re.” Won fi abamo won pamo nigba ti won ri iya. A si ko ewon si orun awon t’o sai gbagbo. Se A oo san won ni esan kan bi ko se ohun ti won n se nise

[34] Ati pe A o ran olukilo kan si ilu kan ayafi ki awon onigbedemuke ilu naa wi pe: “Dajudaju awa sai gbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise.”

[35] Won tun wi pe: “Awa ni dukia ati omo ju (yin lo); won ko si nii je wa niya.”

[36] So pe: “Dajudaju Oluwa mi, O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran), sugbon opolopo awon eniyan ko mo

[37] Ki i se awon dukia yin, ki i si se awon omo yin ni nnkan ti o maa mu yin sunmo Wa pekipeki afi eni ti o ba gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni esan ilopo wa fun nipa ohun ti won se nise. Won yo si wa ninu awon ipo giga (ninu Ogba Idera) pelu ifayabale

[38] Awon t’o n se ise aburu nipa awon ayah Wa, (ti won lero pe) awon mori bo ninu iya; awon wonyen ni won maa mu wa sinu Ina.”

[39] So pe: “Dajudaju Oluwa mi, O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re fun elomiiran. Ati pe ohunkohun ti e ba na, Oun l’O maa fi (omiran) ropo re. O si l’oore julo ninu awon olupese.”

[40] Ni ojo ti Allahu yoo ko gbogbo won jo patapata, leyin naa O maa so fun awon molaika pe: “Se eyin ni won n josin fun?”

[41] Won a so pe: “Mimo fun O! Iwo ni Alaabo wa, ki i se awon. Rara (won ko josin fun wa). Awon alujannu ni won n josin fun; opolopo won ni won gba alujannu gbo

[42] Nitori naa, ni oni apa kan yin ko ni ikapa anfaani, ko si ni ikapa inira fun apa kan. A si maa so fun awon t’o sabosi pe: “E to iya Ina ti e n pe niro wo.”

[43] Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, won a wi pe: “Ki ni eyi bi ko se okunrin kan ti o fe se yin lori kuro nibi nnkan ti awon baba yin n josin fun.” Won tun wi pe: “Ki ni eyi bi ko se adapa iro.” Ati pe awon t’o sai gbagbo wi nipa ododo nigba ti o de ba won pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”

[44] A o fun won ni awon tira kan kan ti won n ko eko ninu re, A o si ran olukilo kan kan si won siwaju re

[45] Awon t’o siwaju won naa pe ododo niro. (Owo awon wonyi) ko si ti i te ida kan ida mewaa ninu ohun ti A fun (awon t’o siwaju). Sibesibe won pe awon Ojise Mi ni opuro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri

[46] So pe: “Ohun kan soso ni mo n se waasi re fun yin pe, e duro nitori ti Allahu ni meji ati ni eyo kookan. Leyin naa, ki e ronu jinle. Ko si alujannu kan lara eni yin. Ko si je kini kan bi ko se olukilo fun yin siwaju iya lile kan.”

[47] So pe: “Emi ko bi yin leere owo-oya kan, eyin le kuku lowo yin. Ko si owo oya mi (lodo eni kan) afi lodo Allahu. Oun si ni Arinu-rode gbogbo nnkan.”

[48] So pe: “Dajudaju Oluwa mi, Onimo-ikoko l’O n mu ododo wa.”

[49] So pe: “Ododo ti de. Iro (esu) ko le mu nnkan be, ko si le da nnkan pada (leyin to ti ku).”

[50] So pe: “Ti mo ba sina, mo sina fun emi ara mi ni. Ti mo ba si mona, nipa ohun ti Oluwa mi fi ranse si mi ni imisi ni. Dajudaju Oun ni Olugbo, Alasun-unmo eda.”

[51] Ti o ba je pe o le ri (esin won ni) nigba ti eru ba de ba won (ni Ojo Ajinde, o maa ri i pe), ko nii si imoribo kan (fun won). A si maa gba won mu lati aye t’o sunmo

[52] Won yoo wi pe: “A gbagbo ninu (al-Ƙur’an bayii).” Bawo ni owo won se le te igbagbo ododo lati aye t’o jinna (iyen, orun).”

[53] Won kuku ti sai gbagbo ninu re siwaju (nile aye). Won si n soro nipa ikoko lati aye t’o jinna (iyen, ile aye)

[54] A si fi gaga si aarin awon ati ohun ti won n soju kokoro re gege bi A ti se fun awon egbe won ni isaaju. Dajudaju won wa ninu iyemeji t’o gbopon (nipa Ojo Ajinde)

Olùdásílẹ̀

Surah 35

[1] Gbogbo ope n je ti Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile, (Eni ti) O se awon molaika alapa meji ati meta ati merin ni Ojise. O n se alekun ohun ti O ba fe lara eda. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[2] Ohunkohun ti Allahu ba si ona re sile ninu ike fun awon eniyan, ko si eni ti o le da a duro. Ohunkohun ti O ba si mu dani, ko si eni ti o le mu un wa leyin Re. Oun si ni Alagbara, Ologbon

[3] Eyin eniyan, e ranti idera Allahu lori yin. Nje eledaa kan yato si Allahu tun wa ti o n pese fun yin lati inu sanmo ati ile? Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo

[4] Ti won ba pe o ni opuro, won kuku ti pe awon Ojise kan ni opuro siwaju re. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

[5] Eyin eniyan, dajudaju adehun Allahu ni ododo. E ma se je ki isemi aye tan yin je. Ki e si ma se je ki (Esu) eletan tan yin je

[6] Dajudaju Esu ni ota fun yin. Nitori naa, e mu un ni ota. O kan n pe awon ijo re nitori ki won le je ero inu Ina t’o n jo fofo

[7] Awon t’o sai gbagbo, iya lile n be fun won. Awon t’o si gbagbo ni ododo, ti won se ise rere, aforijin ati esan t’o tobi n be fun won

[8] Se eni ti won se ise aburu owo re ni oso fun, ti o si n ri i ni (ise) daadaa, (l’o fe banuje le lori?) Dajudaju Allahu n si eni ti O ba fe lona. O si n fi ona mo eni ti O ba fe. Nitori naa, ma se banuje nitori tiwon. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti won n se

[9] Allahu ni Eni ti O fi awon ategun ranse. (Ategun naa) si maa tu esujo soke. A si fi fun ilu (ti ile re) ti ku lomi mu. A si fi ta ile naa ji leyin ti o ti ku. Bayen ni ajinde (eda yo se ri)

[10] Eni ti o ba n fe iyi dajudaju ti Allahu ni gbogbo iyi patapata. Odo Re ni oro daadaa n goke lo. O si n gbe ise rere goke (si odo Re). Awon ti won n pete awon aburu, iya lile n be fun won. Ete awon wonyen si maa parun

[11] Allahu da yin lati ara erupe. Leyin naa, (O tun da yin) lati ara ato. Leyin naa, O se yin ni ako-abo. Obinrin kan ko nii loyun, ko si nii bimo afi pelu imo Re. Ati pe A o nii fa emi elemii-gigun gun, A o si ni se adinku ninu ojo ori (elomiiran), afi ki o ti wa ninu tira kan. Dajudaju iyen rorun fun Allahu

[12] Awon odo meji naa ko dogba; eyi ni (omi) didun gan-an, ti mimu re n lo tinrin lofun. Eyi si ni (omi) iyo t’o moro. Ati pe ninu gbogbo (omi odo wonyi) l’e ti n je eran (eja) tutu. E si n wa kusa awon ohun oso ti e n wo (sara). O si n ri awon oko oju-omi t’o n la aarin omi koja nitori ki e le wa ninu oore Allahu ati nitori ki e le dupe (fun Un)

[13] (Allahu) n ti oru bo inu osan. O si n ti osan bo inu oru. O ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. TiRe ni ijoba. Awon ti e si n pe leyin Re, won ko ni ikapa kan lori epo koro inu dabinu

[14] Ti e ba pe won, won ko le gbo ipe yin. Ti o ba si je pe won gbo, won ko le da yin lohun. Ati pe ni Ojo Ajinde, won yoo tako bi e se fi won se akegbe fun Allahu. Ko si si eni ti o le fun o ni iro kan (nipa eda ju) iru (iro ti) Onimo-ikoko (fun o nipa won)

[15] Eyin eniyan, eyin ni alaini (ti e ni bukata) si Allahu. Allahu, Oun ni Oloro, Olope

[16] Ti O ba fe, O maa ko yin kuro nile. O si maa mu eda titun wa

[17] Iyen ko si kagara kan ba Allahu

[18] Eleru ese kan ko nii ru eru ese elomiiran. Koda ki eni kan ti eru ese wo lorun ke si (elomiiran) fun abaru eru ese re, won ko nii ba a ru kini kan ninu re, ibaa je ibatan. Awon ti o n sekilo fun ni awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko, ti won si n kirun. Eni ti o ba safomo (ara re kuro ninu iwa ese), o safomo fun emi ara re ni. Odo Allahu si ni abo eda

[19] Afoju ati oluriran ko dogba

[20] Awon ookun ati imole (ko dogba)

[21] Awon iboji ati igbona oorun (ko dogba)

[22] Awon alaaye ati oku ko dogba. Dajudaju Allahu l’O n fun eni ti O ba fe ni oro gbo. Iwo ko si le fun eni ti o wa ninu saree ni oro gbo

[23] Iwo ko je kini kan bi ko se olukilo

[24] Dajudaju Awa fi ododo ran o nise. (O si je) oniroo-idunnu ati olukilo. Ko si ijo kan (siwaju re) afi ki olukilo ti re koja laaarin won

[25] Ti won ba si n pe o ni opuro, awon t’o siwaju won naa kuku pe (oro Allahu) niro (nigba ti) awon Ojise won wa ba won pelu awon eri t’o yanju, awon ipin-ipin Tira ati Tira t’o n tanmole si oro esin

[26] Leyin naa, Mo gba awon t’o sai gbagbo mu. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri

[27] Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O so omi kale lati sanmo? A si fi mu awon eso ti awo re yato sira won jade. Ati pe awon oju ona funfun ati pupa ti awo re yato sira won pelu alawo dudu kirikiri wa ninu awon apata

[28] Ati pe o wa ninu awon eniyan, awon nnkan elemii ati awon eran-osin ti awo won yato sira won, gege bi (awo eso ati apata) wonyen (se yato sira won). Awon t’o n paya Allahu ninu awon erusin Re ni awon onimo (ti won mo pe), dajudaju Allahu ni Alagbara, Alaforijin

[29] Dajudaju awon t’o n ke tira Allahu, ti won n kirun, ti won si n na ninu nnkan ti A se ni arisiki fun won ni ikoko ati ni gbangba, won n nireti si owo kan ti ko nii parun

[30] (Won n se bee) nitori ki Allahu le san won ni esan rere won ati nitori ki O le se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Dajudaju Oun ni Alaforijin, Olope

[31] Ohun ti A fi ranse si o ninu Tira, ohun ni ododo ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re. Dajudaju Allahu ni Onimo-ikoko, Oluriran nipa awon erusin Re

[32] Leyin naa, A jogun tira (al-Ƙur’an) fun awon ti A sa lesa ninu awon erusin Wa. Nitori naa, alabosi t’o n bo emi ara re si wa ninu won. Oluse-deede wa ninu won. Olugbawaju nibi awon ise rere tun wa ninu won pelu iyonda Allahu. Iyen si ni oore ajulo t’o tobi

[33] Awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo inu re. Awon kerewu wura ati okuta olowo iyebiye ni A oo maa fi se oso fun won ninu re. Ati pe aso alaari ni aso won ninu re

[34] Won yoo so pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O mu ibanuje kuro fun wa. Dajudaju Oluwa wa ni Alaforijin, Olope

[35] Eni ti O so wa kale sinu ibugbe gbere ninu oore ajulo Re. Wahala kan ko nii kan wa ninu re. Ikaaare kan ko si nii ba wa ninu re

[36] Ati pe awon t’o sai gbagbo, ina Jahnamo n be fun won. A o nii pa won (sinu re), ambosibosi pe won yoo ku. A o si nii gbe iya re fuye fun won. Bayen ni A se n san gbogbo awon alaigbagbo ni esan

[37] Won yoo maa logun iranlowo ninu re pe: “Oluwa wa, mu wa jade nitori ki a le lo se ise rere, yato si eyi ti a maa n se.” Se A o fun yin ni emi gigun lo to fun eni ti o ba fe lo isiti lati ri i lo ninu asiko naa ni? Olukilo si wa ba yin. Nitori naa, e to iya wo. Ko si nii si alaranse kan fun awon alabosi

[38] Dajudaju Allahu ni Onimo-ikoko awon sanmo ati ile. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda

[39] Oun ni Eni t’O n fi yin se arole lori ile. Nitori naa, eni ti o ba sai gbagbo, (iya) aigbagbo re wa lori re. Aigbagbo awon alaigbagbo ko si nii fun won ni alekun kan lodo Oluwa won bi ko se ibinu. Aigbagbo awon alaigbagbo ko si nii fun won ni alekun kan bi ko se ofo

[40] So pe: “E so fun mi nipa awon orisa yin ti e n pe leyin Allahu, e fi ohun ti won da han mi lori ile? Tabi won ni ipin kan (pelu Allahu) nibi (iseda) awon sanmo? Tabi A fun won ni tira kan, ti won ni eri t’o yanju ninu re? Rara o! Ko si adehun kan ti awon alabosi, apa kan won n se fun apa kan bi ko se etan.”

[41] Dajudaju Allahu l’O n mu awon sanmo ati ile duro sinsin ti won ko fi ye lule. Dajudaju ti won ba si ye lule, ko si eni kan kan ti o maa mu un duro leyin Re. Dajudaju Allahu n je Alafarada, Alaforijin

[42] Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe: "Dajudaju ti olukilo kan ba fi le wa ba awon, dajudaju awon yoo mona taara ju eyikeyii ninu ijo (t’o ti siwaju) lo." Nigba ti olukilo si wa ba won, (eyi) ko se alekun kan fun won bi ko se sisa (fun ododo)

[43] ni ti sise igberaga lori ile ati ni ti ipete aburu. Iya ipete aburu ko si nii ko le eni kan lori afi onise aburu. Se won n reti kini kan bi ko se ise (Allahu lori) awon eni akoko? Nitori naa, o o nii ri iyipada fun ise Allahu. Ani se, o o nii ri iyipada fun ise Allahu

[44] Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won si ni agbara ju awon (wonyi) lo! Ati pe ko si kini kan ninu awon sanmo ati ile ti o le mori bo lowo Allahu. Dajudaju Allahu n je Onimo, Alagbara

[45] Ti o ba je pe Allahu yo (tete) maa mu eniyan pelu ohun ti won se nise ni, iba ti se ku nnkan elemii kan kan mo lori ile. Sugbon O n lo won lara di gbedeke akoko kan. Nigba ti akoko naa ba de, dajudaju Allahu ni Oluriran nipa awon erusin Re

Yāsĩ

Surah 36

[1] Ya sin

[2] (Allahu) bura pelu Al-Ƙur’an tira ogbon

[3] Dajudaju iwo wa ninu awon Ojise

[4] wa lori ona taara (’Islam)

[5] (Al-Ƙur’an je) imisi t’o sokale lati odo Alagbara, Asake-orun

[6] nitori ki o le sekilo fun awon eniyan kan, (awon) ti won ko se ikilo fun awon baba won ri. Nitori naa, afonufora si ni won (nipa imona)

[7] Dajudaju oro naa ti ko le opolopo won lori; won ko si nii gbagbo

[8] Dajudaju Awa ti ko ewon si won lorun. O si ga de agbon (won). Won si ga won lorun soke

[9] Ati pe Awa fi gaga kan siwaju won, gaga kan seyin won; A bo won loju, won ko si riran

[10] Bakan naa ni fun won, yala o kilo fun won tabi o o kilo fun won; won ko nii gbagbo

[11] Eni ti ikilo re (maa wulo fun) ni eni ti o tele Isiti (al-Ƙur’an), ti o si paya Ajoke-aye ni ikoko. Nitori naa, fun un ni iro idunnu nipa aforijin ati esan alapon-onle

[12] Dajudaju Awa, Awa l’A n so awon oku di alaye. A si n se akosile ohun ti won ti siwaju ati oripa (ise owo) won. Gbogbo nnkan ni A se akosile re sinu tira kan t’o yanju

[13] Fi apejuwe kan lele fun won nipa awon ara ilu kan nigba ti awon Ojise wa ba won

[14] (Ranti) nigba ti A ran Ojise meji nise si won. Won pe awon mejeeji ni opuro. A si fi eni keta ro awon mejeeji lagbara. Won si so pe: “Dajudaju awa ni Ojise ti Won ran nise si yin.”

[15] Won wi pe: “Eyin ko je kini kan bi ko se abara bi iru tiwa. Ajoke-aye ko si so nnkan kan kale. Eyin ko si je kini kan bi ko se opuro.”

[16] Won so pe: "Oluwa wa mo pe dajudaju awa ni Ojise ti Won ran nise si yin

[17] Ko si si ojuse kan fun wa bi ko se ise-jije ponnbele.”

[18] Won wi pe: “Dajudaju awa ri ami aburu lara yin. Ti e o ba jawo (nibi ipepe yin), dajudaju a maa so yin loko pa. Iya eleta-elero yo si je yin lati odo wa.”

[19] Won so pe: "Ami aburu yin n be pelu yin. Se nitori pe won se isiti fun yin (l’e fi ri ami aburu lara wa)? Ko ri bee! Ijo alakoyo ni yin ni

[20] Okunrin kan sare de lati opin ilu naa, o wi pe: “Eyin eniyan mi, e tele awon Ojise naa

[21] E tele eni ti ko beere owo-oya kan ni owo yin. Olumona si ni won

[22] Ki ni o maa mu mi ti emi ko fi nii josin fun Eni ti O pile eda mi? Odo Re si ni won yoo da yin pada si

[23] Se ki ng so awon kan di olohun leyin Allahu ni? Ti Ajoke-aye ba fe fi inira kan mi, isipe won ko le ro mi loro kini kan, won ko si le gba mi la

[24] (Bi emi ko ba josin fun Allahu) nigba naa dajudaju mo ti wa ninu isina ponnbele

[25] Dajudaju emi gbagbo ninu Oluwa Eledaa yin. Nitori naa, e gbo mi.”

[26] Won so pe: “Wo inu Ogba Idera.” O so pe: “Awon eniyan mi iba ni imo

[27] nipa bi Oluwa mi se forijin mi ati (bi) O se fi mi si ara awon alapon-onle (won iba ronu piwada).”

[28] A ko so omo ogun kan kale le awon eniyan re lori lati sanmo leyin re. A o si so (molaika kan) kale (fun iparun won)

[29] (Iparun won) ko je kini kan bi ko se igbe eyo kan; nigba naa ni won di oku kale

[30] Abamo ma ni fun awon erusin naa; ojise kan ko nii wa ba won ayafi ki won maa fi se yeye

[31] Se won ko ri i pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won? (Se won ko ri i pe) dajudaju won ko pada si odo won mo (nile aye) ni

[32] Dajudaju gbogbo won patapata si ni won maa ko wa si odo Wa

[33] Ami ni oku ile je fun won. A so o di aye. A si mu eso jade lati inu re. Won si n je ninu re

[34] A tun se awon ogba dabinu ati ajara sinu ile. A si mu awon odo iseleru se yo lati inu re

[35] nitori ki won le je ninu eso re ati eyi ti won fi owo ara won se! Se won ko nii dupe ni? “nitori ki won le je ninu eso re ki i si se ise owo won. Se won ko nii dupe ni?” Itumo keji duro le ise Allahu lori iseda nnkan oko. Iyen ni pe

[36] Mimo ni fun Eni ti O seda gbogbo nnkan ni orisirisi ninu ohun ti ile n hu jade ati ninu emi ara won ati ninu ohun ti won ko mo. tabi oro imo ero kan tabi imo irori kan tabi eyikeyii imo kan lodi si ayah kan ninu al-Ƙur’an tabi hadith Anabi wa Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) t’o fese rinle o ti sina ni isina ponnbele. “zaoj” ni eyo. “Zaoj” si n tumo si ako tabi abo nigba ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) ba n soro nipa iseda eniyan tabi omo bibi gege bi o se wa ninu surah an-Najm; 53:45 ati surah al-Ƙiyamoh; 75:39. amo ti ikini keji yato sira won ni ona kookan gege bi ako ati abo nnkan didun ati nnkan kikoro a le ri eso mimu tabi eso jije kan ti o maa je orisirisi. Itumo olorisirisi tun lo labe ayah ti a n tose re lowo yii. Nitori naa zaoj ko pon dandan ki o ni itumo ako ati abo nikan. Orisirisi ni “zaoj”; ako je orisi kan

[37] Oru je ami kan fun won, ti A n yo osan jade lati inu re. Nigba naa (ti A ba yo o tan) won yoo tun wa ninu okunkun (ale miiran). ojo keje ni ojo iparan suna omo naa. Bawo ni a o se ka ojo meje naa? Teletele awon kan lero pe koda ki ojo ibimo ku iseju kan ti a o fi bo sinu ojo titun. Bi apeere ti obinrin kan ba bimo ni osan Alaadi

[38] Ati pe oorun yoo maa rin lo si aye re. Iyen ni eto (ti) Alagbara, Onimo

[39] Osupa naa, A ti se odiwon awon ibuso fun un (ti o ti ma maa tobi si i) titi o maa fi pada da bii ogomo ope t’o ti pe

[40] Ko ye fun oorun lati lo asiko osupa. Ko si ye fun ale lati lo asiko osan. Ikookan wa ni opopona roboto t’o n to

[41] O tun je ami fun won pe dajudaju Awa gbe awon aromodomo won gun oko oju-omi t’o kun keke

[42] A tun seda (omiran) fun won ninu iru re ti won yoo maa gun

[43] Ti A ba fe Awa iba te won ri sinu omi. Ko nii si oluranlowo kan fun won. Won ko si nii gba won la

[44] Afi (ki A fi) ike kan lati odo Wa (yo won jade, ki A si tun fun won ni) igbadun aye titi di igba die

[45] (Won maa gbunri) nigba ti A ba so fun won pe: "E sora fun ohun t’o wa niwaju yin ati ohun t’o wa leyin yin nitori ki A le ke yin

[46] Ati pe ayah kan ninu awon ayah Oluwa won ko nii wa ba won afi ki won maa gbunri kuro nibe

[47] Nigba ti A ba si so fun won pe: "E na ninu ohun ti Allahu se ni arisiki fun yin.", awon t’o sai gbagbo yoo wi fun awon t’o gbagbo pe: "Se ki a bo eni ti (o je pe) Allahu iba fe iba bo o (amo ko bo o. Awa naa ko si nii ba A bo o)?” Ki ni eyin bi ko se pe (e wa) ninu isina ponnbele

[48] Won si n wi pe: "Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo

[49] Won ko reti kini kan bi ko se igbe eyo kan soso ti o maa gba won mu nigba ti won ba n se ariyanjiyan lowo

[50] Nigba naa, won ko nii le so asoole kan. Won ko si nii le pada si odo ara ile won

[51] Won a si fon fere oniwo fun ajinde, nigba naa ni won yoo maa sare jade lati inu saree wa si odo Oluwa won

[52] Won a wi pe: "Egbe wa o! Ta ni o ta wa ji lati oju oorun wa?" Eyi ni nnkan ti Ajoke-aye se ni adehun. Awon Ojise si ti so ododo (nipa re)

[53] Ko je kini kan tayo igbe eyo kan soso. Nigba naa ni (awon molaika) yoo ko gbogbo won jo si odo Wa

[54] Nitori naa, ni oni won ko nii se abosi kini kan fun emi kan. A o si nii san yin ni esan afi ohun ti e n se nise

[55] Dajudaju ni oni awon ero inu Ogba Idera yoo kun fun igbadun

[56] Awon ati awon iyawo won yoo wa labe awon iboji, won yo si rogboku sori awon ibusun

[57] Eso wa ninu re fun won. Ohun ti won yoo maa beere fun tun wa fun won pelu

[58] Alaafia ni oro ti o maa wa lati odo Oluwa, Asake-orun

[59] Eyin elese, e bo si oto ni oni

[60] Eyin omo (Anabi) Adam, se Emi ko ti pa yin ni ase pe ki e ma se josin fun Esu? Dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

[61] Ati pe ki e josin fun Mi. Eyi ni ona taara

[62] Ati pe (Esu) kuku ti si opolopo eda lona ninu yin. Se e o nii se laakaye ni

[63] Eyi ni ina Jahanamo ti A n se ni adehun fun yin

[64] E wo inu re ni oni nitori pe eyin je alaigbagbo

[65] Ni oni, A maa di enu won pa. Awon owo won yo si maa ba Wa soro. Awon ese won yo si maa jerii si ohun ti won n se nise

[66] Ti o ba je pe A ba fe, Awa iba fo won loju, won iba si yara wa soju ona, bawo ni won se maa riran na

[67] Ti o ba je pe A ba fe, Awa iba yi won pada si eda miiran ninu ibugbe won. Won ko si nii lagbara lati lo siwaju. Won ko si nii pada seyin

[68] Enikeni ti A ba fun ni emi gigun lo, A oo so eda re di ole, se won ko nii se laakaye ni

[69] A o ko Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) ni ewi. Ko si ro o lorun (lati kewi). Ki ni ohun (ti A fi ranse si i) bi ko se iranti ati al-Ƙur’an ponnbele

[70] nitori ki o le sekilo fun eni ti o je alaaye ati nitori ki oro naa le ko lori awon alaigbagbo

[71] Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A seda ninu ohun ti A fi owo Wa se (ti o je) awon eran-osin fun won? Won si ni ikapa lori won

[72] A te won lori ba fun won; won n gun ninu won, won si n je ninu won

[73] Awon anfaani ati ohun mimu tun wa fun won ninu re. Se won ko nii dupe ni

[74] Won so awon kan di olohun leyin Allahu nitori ki won le saranse fun won

[75] Won ko si le se aranse fun won; sebi awon orisa ni omo ogun ti A maa ko wo inu Ina fun awon aborisa (lati fi je won niya)

[76] Nitori naa, ma se je ki oro won ba o ninu je. Dajudaju Awa mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n safi han re

[77] Se eniyan ko ri i pe dajudaju Awa l’A seda re lati inu ato? (Sebi leyin) igba naa l’o di alatako ponnbele

[78] Ati pe o fi akawe lele nipa Wa. O si gbagbe iseda re. O wi pe: "Ta ni O maa so egungun di alaaye nigba ti o ti kefun

[79] So pe: "Eni ti O seda re nigba akoko l’O maa so o di alaaye. Oun si ni Onimo nipa gbogbo eda

[80] (Oun ni) Eni ti O mu ina jade fun yin lati ara igi tutu. E si n fi ko ina

[81] Nje Eni ti O seda awon sanmo ati ile ko ni agbara lati da iru won (miiran) bi? Rara (O ni agbara). Oun si ni Eledaa, Onimo

[82] Ase Re nigba ti O ba gbero kini kan ni pe, O maa so fun un pe "Je bee." O si maa je bee

[83] Nitori naa, mimo ni fun Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

Àwọn tó ń tò lẹ́sẹẹsẹ

Surah 37

[1] (Allahu bura pelu) awon molaika oluto-lowoowo taara

[2] ati awon molaika t’o n wo esujo kiri taara

[3] ati awon molaika onke-tira iranti

[4] Dajudaju Olohun yin, Okan soso ni

[5] Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Oun si ni Oluwa awon ibuyo oorun

[6] Dajudaju Awa fi awon irawo se sanmo ile aye ni oso

[7] ati iso nibi (aburu) gbogbo esu olorikunkun

[8] (Awon esu) ko si nii le teti si ijo (molaika t’o wa ni) aye giga julo (ninu sanmo). (Awon molaika) yo si maa ku (awon esu) loko (eta irawo) ni gbogbo agbegbe (sanmo)

[9] Won n le won danu. Iya ailopin si wa fun won

[10] (Won ko nii gbo oro ni kikun) ayafi eni ti o ba ri oro ajigbo gbe, nigba naa (ni molaika) yo si fi eta irawo ina t’o maa jo o tele e

[11] Bi won leere wo pe se awon ni iseda won lagbara julo ni tabi awon (eniyan) ti A da? Dajudaju Awa da won lati ara erupe t’o le mora won

[12] Rara (ko jora won); iwo seemo (nipa al-Ƙur’an), awon si n se yeye

[13] Ati pe nigba ti won ba se iranti fun won, won ko nii lo iranti

[14] Nigba ti won ba tun ri ami kan, won yoo maa se yeye

[15] Won si wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se idan ponnbele

[16] Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo tun gbe wa dide ni

[17] Se ati awon baba wa, awon eni akoko

[18] So pe: "Bee ni. Eyin yo si di eni yepere

[19] Nitori naa, igbe eyo kan ma ni. Nigba naa ni won yoo maa wo sun

[20] Won a wi pe: "Egbe wa! Eyi ni Ojo esan

[21] Eyi ni ojo Idajo eyi ti e n pe niro

[22] E ko awon t’o sabosi jo, awon iyawo won ati ohun ti won n josin fun

[23] leyin Allahu. Ki e si juwe won si oju ona ina Jehim

[24] E da won duro na, dajudaju won maa bi won leere ibeere

[25] Ki ni ko je ki e ranra yin lowo

[26] Rara, won ti juwo juse sile ni oni ni

[27] Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere

[28] (Awon eniyan) wi pe: "Dajudaju eyin l’e n gba otun wole si wa lara (lati si wa lona)

[29] (Awon alujannu) wi pe: "Rara o (awa ko), eyin ni e ko je onigbagbo ododo

[30] Ati pe awa ko ni agbara kan lori yin, sugbon eyin je ijo olutayo-enu ala

[31] Oro Oluwa wa si ko le wa lori pe dajudaju awa yoo to Ina wo

[32] Nitori naa, a si yin lona. Dajudaju awa naa si je olusina

[33] Dajudaju ni ojo yen, akegbe ni won ninu Iya

[34] Dajudaju bayen ni Awa yoo ti se pelu awon elese

[35] Dajudaju nigba ti won ba so fun won pe "Ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu.", won yoo maa segberaga

[36] Won si n wi pe: "Se a maa fi awon orisa wa sile nitori elewi were kan

[37] Ko ri bee. O mu ododo wa ni. O si n jerii si ododo awon Ojise naa

[38] Dajudaju e maa to iya eleta-elero wo

[39] A o nii san yin ni esan kan afi ohun ti e n se nise

[40] Afi awon erusin Allahu, awon eni esa

[41] Ti awon wonyen si ni arisiki ti won ti mo

[42] awon eso. Awon si ni alapon-onle

[43] ninu awon Ogba Idera

[44] Lori awon ite ni won yoo ti koju sira won

[45] Won yoo maa gbe ife oti mimo kaa kiri odo won

[46] Funfun ni (oti naa). O n dun lenu awon t’o maa mu un

[47] Ko si ipalara kan fun won ninu re, won ko si nii hunrira lori re

[48] Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, awon eleyinju ege yo si wa lodo won

[49] Won da bi tinu eyin. o tun je ki a mo pe won ko reti ike kan kan lorun ni tiwon. Ti o ba je pe won n reti ike kan ni orun

[50] Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere

[51] Onsoro kan ninu won yoo so pe: "Dajudaju emi ni ore kan

[52] ti o n wi pe, “Se dajudaju iwo wa ninu awon onigbagbo ninu Ojo Ajinde

[53] Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo san wa ni esan ni?”

[54] O so pe: "Se eyin yoo yoju wo (eni naa ti ko gbagbo ninu Ojo ajinde)

[55] O yoju wo o. O si ri i laaarin gbungbun ninu ina Jehim

[56] O (si) so pe: "Mo fi Allahu bura, iwo fee ko iparun ba mi tan

[57] Ati pe ti ki i ba se idera Oluwa mi ni, emi naa iba wa ninu eni ti won maa mu wa sinu Ina

[58] Awa ko sa nii ku mo bayii

[59] Afi iku wa akoko. Won ko si nii je awa niya

[60] Dajudaju eyi, ohun ni erenje nla

[61] Nitori iru eyi, ki awon olusesin maa sesin lo

[62] Nje iyen l’o loore julo ni ibudesi ni tabi igi zaƙum (igi elegun-un)

[63] Dajudaju Awa se e ni adanwo fun awon alabosi

[64] Dajudaju ohun ni igi kan ti o maa hu jade lati idi ina Jehim

[65] Eso re da bi ori awon esu

[66] Dajudaju won yoo maa je ninu re. Nitori naa, won yoo fi kun inu won bamubamu

[67] Leyin naa, dajudaju won yoo mu nnkan mimu awoyunweje gbigbona le e lori

[68] Leyin naa, dajudaju ibupadasi won ni ina Jehim

[69] Dajudaju won ba awon baba won ni olusina

[70] Awon naa si n yara tele oripa won

[71] Dajudaju opolopo awon eni akoko ti sina siwaju won

[72] Dajudaju A ti ran awon olukilo si won

[73] Nitori naa, wo bi atubotan awon eni-akilo-fun ti ri

[74] Afi awon erusin Allahu, awon eni esa

[75] Dajudaju (Anabi) Nuh pe Wa. A si dara ni olujepe

[76] A gba oun ati awon ara ile re la kuro ninu ibanuje nla

[77] A da awon aromodomo re si leyin re

[78] A si fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin

[79] Alaafia ki o maa ba (Anabi) Nuh laaarin gbogbo eda

[80] Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

[81] Dajudaju oun wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo

[82] Leyin naa, A te awon yooku ri sinu agbami

[83] Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim wa ninu ijo (ti o tele ilana) re

[84] (E ranti) nigba ti oun naa doju ko Oluwa re pelu okan mimo

[85] (Ranti) nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: "Ki ni e n josin fun

[86] Se e n gbero lati so iro di olohun leyin Allahu

[87] Ki si ni ero okan yin si Oluwa gbogbo eda?”

[88] O siju wo awon irawo gan-an

[89] O si so pe: "Dajudaju o re mi

[90] Nitori naa, won pa a ti, won si lo

[91] Nigba naa, o lo si odo awon orisa won. O si so pe: "Se e o nii jeun ni

[92] Ki ni o se yin ti e o soro

[93] Nigba naa, o doju lilu ko won pelu owo otun (o si run won womuwomu)

[94] (Awon aborisa) sare wa doju ko o

[95] O so pe: "Se e oo maa josin fun nnkan ti e gbe kale lere ni

[96] Allahu l’O si da eyin ati nnkan ti e n se nise

[97] Won wi pe: "E mo ile kan fun un, ki e si ju u sinu ina

[98] Won gbero ete si i. A si so won di eni yepere

[99] O so pe: "Dajudaju mo maa lo si (ilu ti) Oluwa mi (pa mi lase lati lo). O si maa to mi sona (lati de ibe)

[100] Oluwa mi, ta mi lore omo ninu awon eni rere

[101] A si fun un ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin alafarada

[102] Nigba ti (omo naa) dagba, ti o to ba (baba re) se ise, (baba re) so pe: "Omo mi, dajudaju emi la ala pe dajudaju mo n dunbu re. Nitori naa, woye si i, ki ni o ri si i." O so pe: "Baba mi, se ohun ti Won pa lase fun o. O maa ba mi ninu awon onisuuru, ti Allahu ba fe

[103] Nigba ti awon mejeeji juwo juse sile, ti (Anabi ’Ibrohim) si doju (omo) re bole

[104] A pe e (bayii) pe, ’Ibrohim

[105] o kuku ti mu ala naa se. Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

[106] Dajudaju eyi, ohun ni adanwo ponnbele

[107] A si fi agbo nla serapada re

[108] A tun fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin

[109] Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ibrohim

[110] Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

[111] Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo

[112] A tun fun un ni iro idunnu (nipa bibi) ’Ishaƙ, (o maa je) Anabi. (O si maa wa) ninu awon eni rere

[113] Ati pe A fun oun ati ’Ishaƙ ni ibukun. Eni rere ati alabosi ponnbele (t’o n sabosi si) emi ara re wa ninu aromodomo awon mejeeji

[114] Dajudaju A soore fun (Anabi) Musa ati Harun

[115] A gba awon mejeeji ati ijo awon mejeeji la kuro ninu ibanuje nla

[116] A tun saranse fun won. Awon ni won je olubori (ota won)

[117] A si fun awon mejeeji ni Tira t’o yanju

[118] A tun fi awon mejeeji mona taara

[119] A fun awon mejeeji ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin

[120] Alaafia ki o maa ba (Anabi) Musa ati Harun

[121] Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

[122] Dajudaju awon mejeeji wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo

[123] Dajudaju (Anabi) ’Ilyas wa ninu awon Ojise

[124] (E ranti) nigba ti o so fun ijo re pe: "Se e o nii beru Allahu ni

[125] Se e oo maa pe orisa kan, e si maa fi Eni t’O dara julo ninu awon eledaa sile, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Oun l’O si dara julo ninu awon oludajo. (surah al-’A‘rof 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Oun si yara julo ninu awon onisiro. (surah al-’Ani‘am 6:62) oludajo alaaanu ibaa mo bii omo ina igun afi ki Allahu je Eledaa re. Koda adamo owo ati okowo ti won so di “oro-Aje. Awon t’o n bo elomiiran naa n sora won di olupese. Yato si pe Allahu ti fi rinle pe Oun nikan ni Olupese fun gbogbo eda Re. Ti eyi ko ba ti i da awon kan loju bee ti won si fe gbe gbogbo ipese olukuluku lori iwon ninu aanu ti Allahu fi si awon eda kan lokan ni won fi di alaaanu. Nitori naa Allahu ni Alaaanu julo ninu awon alaaanu

[126] (e n fi) Allahu (sile), Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko

[127] Won si pe e ni opuro. Nitori naa, won maa mu won wa sinu Ina

[128] Afi awon erusin Allahu, awon eni esa

[129] A fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin

[130] Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ilyas

[131] Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

[132] Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo

[133] Dajudaju (Anabi) Lut wa ninu awon Ojise

[134] (E ranti) nigba ti A gba oun ati gbogbo awon ara ile re la

[135] Ayafi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare)

[136] Leyin naa, A pa awon yooku run

[137] Dajudaju eyin naa kuku n gba odo won koja laaaro-laaaro

[138] ati ni alaale. Se e o nii se laakaye ni

[139] Dajudaju (Anabi) Yunus kuku wa ninu awon Ojise

[140] (E ranti) nigba ti o sa lo sinu oko oju-omi t’o kun keke

[141] O si ba won muje po. O si wa ninu awon ti aje si mo lori

[142] Nitori naa, eja gbe e mi; o si n da ara re lebi

[143] Nitori naa, ti ko ba je pe o wa ninu awon olusafomo fun Allahu

[144] dajudaju iba wa ninu eja titi di ojo ti won yoo gbe eda dide

[145] Nitori naa, A ju u si ori ile gbansasa leti omi. O si je alailera

[146] A si mu igi Yeƙtin hu jade lati siji bo o

[147] A tun ran an nise si oke marun-un (eniyan) tabi ki won lekun si i

[148] Won gbagbo ni ododo. A si fun won ni igbadun titi di igba die

[149] Bi won leere wo pe: "Se Oluwa re l’o ni awon omobinrin, tiwon si ni omokunrin

[150] Tabi A da awon molaika ni obinrin, ti awon si je elerii

[151] Gbo, ninu iro won ni pe dajudaju won n wi pe

[152] Allahu bimo." Dajudaju opuro ni won

[153] Se (Allahu) sesa awon omobinrin lori awon omokunrin ni

[154] Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii

[155] Se e o nii lo iranti ni

[156] Tabi e ni eri t’o yanju lowo ni

[157] E mu tira yin wa nigba naa ti e ba je olododo

[158] Won tun fi ibatan saaarin (Allahu) ati alujannu! Awon alujannu si ti mo pe dajudaju won kuku maa mu awon wa sinu Ina ni

[159] Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re)

[160] Afi awon erusin Allahu, awon eni esa

[161] Dajudaju eyin ati nnkan ti e n josin fun (leyin Allahu)

[162] e o le fi si eni kan kan lona

[163] afi eni ti o ba fe wo inu ina Jehim

[164] Ko si eni kan ninu awa (molaika) afi ki o ni ibuduro ti won ti mo

[165] Dajudaju awa, a kuku wa ni owoowo

[166] Ati pe dajudaju awa, awa kuku ni olusafomo (fun Allahu)

[167] Won kuku n wi pe

[168] Ti o ba je pe dajudaju a ba ni (tira) iranti kan ninu (awon tira) awon eni akoko

[169] dajudaju awa iba je erusin Allahu, awon eni esa

[170] Sugbon won sai gbagbo ninu (Allahu). Laipe won maa mo

[171] Dajudaju oro Wa ti siwaju fun awon erusin Wa, awon Ojise

[172] Dajudaju awon, awon l’a kuku maa saranse fun

[173] Ati pe dajudaju awon omo ogun Wa, awon kuku ni olubori

[174] Nitori naa, seri kuro lodo won fun igba die

[175] Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo

[176] Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju

[177] Nigba ti o ba sokale si agboole won, owuro ojo naa yo si buru fun awon eni-akilo-fun

[178] Kuro lodo won titi di igba kan na

[179] Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo

[180] Mimo ni fun Oluwa re, Oluwa agbara, tayo ohun ti won n fi royin (Re)

[181] Ki alaafia maa ba awon Ojise

[182] Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

Ṣọ̄d

Surah 38

[1] Sod. (Allahu bura pelu) al-Ƙur’an, tira iranti

[2] Sibesibe awon t’o sai gbagbo wa ninu igberaga ati iyapa (ododo)

[3] Meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won. Nigba naa, won kigbe too nigba ti ko si ibusasi kan

[4] Won seemo pe olukilo kan ninu won wa ba won. Awon alaigbagbo si wi pe: "Eyi ni opidan, opuro

[5] Se o maa so awon orisa di Olohun Okan soso ti A oo maa josin fun ni? Dajudaju eyi ma ni nnkan iyanu

[6] Awon asiwaju ninu won si lo (kaakiri lati wi fun awon omoleyin won) pe: "E maa ba (iborisa) lo, ki e si duro sinsin ti awon orisa yin. Dajudaju eyi (jije okan soso Allahu) ni nnkan ti won n gba lero (lati fi pa awon orisa yin run)

[7] Awa ko gbo eyi ninu esin ikeyin (iyen, esin kristieniti) . Eyi ko je kini kan bi ko se adapa iro

[8] Se Won so Iranti kale fun un laaarin wa ni?" Rara, won wa ninu iyemeji nipa Iranti Mi (ti Mo sokale ni). Rara, won ko ti i to iya Mi wo ni

[9] Tabi (se) awon ni won ni awon apoti oro Oluwa re, Alagbara, Olore

[10] Tabi tiwon ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohun ti n be laaarin mejeeji? Ti o ba ri bee, ki won wa awon ona lati fi gunke wa (ba Wa)

[11] A maa segun omo ogun t’o wa nibe yen ninu omo ogun onijo

[12] Awon ijo Nuh, ijo ‘Ad ati Fir‘aon, eleekan, won pe ododo niro siwaju won

[13] Ijo Thamud, ijo Lut ati awon ara ’Aekah, awon wonyen (tun ni) awon ijo (t’o pe ododo niro)

[14] Ko si eni kan ninu won ti ko pe awon Ojise ni opuro. Nitori naa, iya Mi si ko le won lori

[15] Awon wonyi ko reti kini kan tayo igbe eyo kan, ti ko nii si idapada (tabi idaduro) kan fun un (t’o ba de)

[16] Won wi pe: "Oluwa wa, yara fi iwe ise wa (ati esan wa) le wa lowo siwaju Ojo isiro-ise

[17] Se suuru lori nnkan ti won n so. Ki o si seranti itan erusin Wa, (Anabi) Dawud, alagbara. Dajudaju o je oluronupiwada

[18] Dajudaju Awa te awon apata lori ba ti won n se afomo pelu re (fun Allahu) ni asale ati nigba ti oorun ba yo

[19] Ati awon eye naa, A ko won jo fun un. Ikookan (won) n tele ase re (lati safomo fun Allahu)

[20] Ati pe A fun ijoba re ni agbara. A si fun un ni ipo Anabi ati eko oro ati idajo

[21] Nje iro awon onija ti de odo re; nigba ti won pon ogiri ile ijosin

[22] Nigba ti won wole to (Anabi) Dawud, eru ba a lati ara won. Won so pe: "Ma se beru. Onija meji (ni wa). Apa kan wa tayo enu-ala si apa kan. Nitori naa, dajo laaarin wa pelu ododo. Ma sabosi. Ki o si to wa si ona taara

[23] Dajudaju eyi ni arakunrin mi. O ni abo ewure mokandin-logorun-un. Emi si ni abo ewure eyo kan. O si so pe: "Fa a le mi lowo. O si bori mi ninu oro

[24] (Anabi Dawud) so pe: "O ti sabosi si o nipa bibeere abo ewure tire mo awon abo ewure tire. Dajudaju opolopo ninu awon olubada-nnkanpo, apa kan won maa n tayo enu-ala lori apa kan afi awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Die si ni won. (Anabi) Dawud si mo daju pe A kan fi (ibeere naa) sadanwo fun oun ni. Nitori naa, o toro aforijin lodo Oluwa re (nipa aiteti gbo oro lenu eni- afesunkan). O doju bole lati fori kanle. O si ronu piwada (sodo Allahu). onka iyawo won le po ni onka ki i se ni ti igbadun adun-ara bi ko se pe Allahu (subhanahu wa ta'ala) fe ko Anabi Dawud ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni eko igbejo nitori pe Allahu (subhanahu wa ta'ala) fe fi se adajo laaarin awon ijo re. Aiteti gbo oro lenu eni-afesunkan ni asise t’o sele si Anabi Dawud ('alaehi-ssolatu wa-ssalam). Eyi naa si ni ohun ti o toro aforijin Olohun fun

[25] Nitori naa, A saforijin iyen fun un. Dajudaju isunmo (Wa) ati abo rere si wa fun un lodo Wa

[26] (Anabi) Dawud, dajudaju Awa se o ni arole lori ile. Nitori naa, dajo laaarin awon eniyan pelu ododo. Ma se tele ife-inu nitori ki o ma baa sina kuro loju ona (esin) Allahu. Dajudaju awon t’o n sonu kuro ninu esin Allahu, iya lile wa fun won nitori pe won gbagbe Ojo isiro-ise

[27] A ko seda sanmo, ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji pelu iro. (Iro), iyen ni ero awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo ninu Ina

[28] Se ki A se awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere bi (A o ti se) awon obileje lori ile? Tabi se ki A se awon oluberu (Mi bi A o ti se) awon asebi

[29] (Eyi ni) Tira ibukun ti A so kale fun o nitori ki won le ronu jinle nipa awon ayah re ati nitori ki awon onilaakaye le lo iranti

[30] A fi (Anabi) Sulaemon ta (Anabi) Dawud lore. Erusin rere ni. Dajudaju oluseri sodo (Allahu) ni (nipa ironupiwada)

[31] (Ranti) nigba ti won ko awon esin akawooja-leri asaretete wa ba a ni irole

[32] o so pe: "Dajudaju emi feran ife ohun rere (iyen, awon esin naa) dipo iranti Oluwa Mi (iyen, irun ‘Asr) titi oorun fi wo

[33] E da won pada sodo mi. "O si bere si i fi ida ge won ni ese ati ni orun

[34] Dajudaju A dan (Anabi) Sulaemon wo. A ju abara kan sori aga re. Leyin naa, (Anabi Sulaemon) seri pada (pelu ironupiwada). Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni iyawo t’o to ogorun-un labe ofin eto (iyen ni pe Allahu s.w.t. l’O se e ni eto fun un). Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) si fi Allahu bura ni ojo kan pe ki i se ara oruka Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni awo Anabi Sulaemon wa. Bawo wa ni o se maa je pe nipase oruka Anabi Sulaemon ni awo re fi maa kuro lara re si ara esu alujannu nigba ti Anabi Sulaemon ki i se opidan? Anabi Sulaemon ko si fi oruka joba ambosibosi pe nigba ti ko ba si oruka re lowo re l’o maa fun elomiiran ni aye lati di oba! E tun wo itose-oro fun surah al-Baƙorah; 2:102. W-Allahu ’a‘lam

[35] O so pe: "Oluwa mi, fori jin mi. Ki O si ta mi ni ore ijoba kan eyi ti ko nii to si eni kan kan mo leyin mi. Dajudaju Iwo, Iwo ni Olore

[36] Nitori naa, A te ategun ba fun un. O n fe pelu ase re ni irorun sibi ti o ba fe

[37] Ati awon esu alujannu; gbogbo awon omole ati awon awakusa (ni A te ba fun un)

[38] Ati awon (alujannu) miiran ti won fi ewon de mole (A te won ba fun un)

[39] Eyi ni ore Wa. Nitori naa, fi tore tabi ki o mu un dani lai la isiro lo (lorun)

[40] Dajudaju isunmo (Wa) ati abo rere si wa fun un ni odo Wa

[41] Seranti erusin Wa, (Anabi) ’Ayyub. Nigba ti o pe Oluwa re (pe): "Dajudaju Esu ti ko inira (aisan) ati iya ba mi

[42] (Molaika so fun un pe): "Fi ese re janle. Eyi ni omi iwe tutu ati omi mimu (fun iwosan re)

[43] A si ta a lore awon ara ile re (pada) ati iru won pelu won. (O je) ike lati odo Wa ati iranti fun awon onilaakaye

[44] Fi owo re mu idi igi koriko tutu ki o fi lu (iyawo) re. Ma se yapa ibura re. Dajudaju Awa ri (’Ayyub) ni onisuuru. Erusin rere ni. Dajudaju oluseri si odo Allahu ni (nipa ironupiwada)

[45] Seranti awon erusin Wa, (Anabi) ’Ibrohim, ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub; awon alagbara, oluriran (nipa esin)

[46] Dajudaju Awa sa won lesa pelu esa kan; iranti Ile Ikeyin

[47] Dajudaju won wa ninu awon eni esa, eni rere julo ni odo Wa

[48] Seranti (awon Anabi) ’Ismo‘il, al-Yasa‘ ati Thul-Kifl. Ikookan won wa ninu awon eni rere julo

[49] Eyi ni iranti. Ati pe dajudaju abo rere wa fun awon oluberu (Allahu)

[50] Awon Ogba Idera gbere (ni). Won si maa si awon ilekun re sile fun won

[51] Won yoo rogboku ninu re. Won yoo maa beere fun awon eso pupo ati ohun mimu ninu re

[52] Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, ti ojo ori won ko jura won lo yo si wa ni odo won

[53] Eyi ni ohun ti Won n se ni adehun fun yin fun Ojo isiro-ise

[54] Dajudaju eyi ni arisiki Wa. Ko si nii tan

[55] Eyi (ri bee). Ati pe dajudaju abo buruku ni ti awon alagbeere (si Allahu)

[56] Ina Jahanamo ni won yo wo. O si buru ni ibugbe

[57] Eyi (ri bee). Nitori naa, ki won to o wo; omi gbigbona ati awoyunweje

[58] Orisirisi (iya) miiran bi iru re (tun wa fun won)

[59] Eyi ni ijo kan t’o maa wo inu Ina pelu yin. (Awon asiwaju ninu Ina si maa wi pe:) "Ko si maawole-maarora fun won." Dajudaju won yoo wo inu Ina ni

[60] (Awon omoleyin ninu Ina) maa wi pe: "Rara, eyin naa ko si maawole-maarora fun yin. Eyin l’e pe wa sibi eyi (t’o bi Ina)." O si buru ni ibugbe

[61] Won (tun) wi pe: "Oluwa wa, eni ti o pe wa (sibi iya) yii, se alekun adipele iya fun un ninu Ina

[62] Won tun wi pe: "Ki lo sele si wa ti a o ri awon okunrin kan, awon ti a n ka mo awon eni buruku

[63] Sebi a fi won se yeye tabi awon oju ti fo won ni (l’a o fi ri won ninu Ina)

[64] Dajudaju iyen, ariyanjiyan awon ero inu Ina, ododo ma ni

[65] So pe: "Emi ni olukilo. Ati pe ko si olohun ti ijosin to si ayafi Allahu, Okan soso, Olubori

[66] Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji, Alagbara, Alaforijin

[67] So pe: "(al-Ƙur’an) ni iro nla

[68] Eyin si n gbunri kuro nibe

[69] Emi ko si nimo nipa awon molaika ti o wa ni aye giga nigba ti won n saroye

[70] Ki ni won fi ranse si mi bi ko se pe emi ni olukilo ponnbele

[71] (Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: "Dajudaju Emi yoo da abara kan lati inu erupe

[72] Nigba ti Mo ba se e t’o dogba jale tan, ti Mo si fe ninu ategun emi ti Mo da sinu re, nigba naa e doju bole fun un ni oluforikanle-kini

[73] Gbogbo awon molaika patapata si fori kanle ki i

[74] Ayafi ’Iblis, ti o segberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo

[75] (Allahu) so pe: "’Iblis, ki l’o ko fun o lati fori kanle ki ohun ti Mo fi owo Mi mejeeji da? Se o segberaga ni tabi o wa ninu awon eni giga

[76] O wi pe: "Emi loore julo si oun; O da emi lati ara ina. O si da oun lati ara erupe amo

[77] (Allahu) so pe: "Jade kuro ninu (Ogba Idera) nitori pe dajudaju iwo ni eni eko

[78] Ati pe dajudaju egun Mi yoo wa lori re titi di Ojo esan

[79] (Esu) wi pe: "Oluwa mi, lo mi lara titi di ojo ti Won yoo gbe eda dide

[80] (Allahu) so pe: "Dajudaju iwo wa ninu awon ti won maa lo lara

[81] titi di ojo akoko ti A ti mo

[82] (Esu) wi pe: "Mo fi agbara Re bura, dajudaju emi yoo ko gbogbo won sinu isina

[83] afi awon erusin Re, awon eni esa ninu won

[84] (Allahu) so pe: "Ododo (ni ibura Mi), ododo si ni Emi n so, (pe)

[85] dajudaju Mo maa fi iwo ati gbogbo awon t’o ba tele o ninu won kun inu ina Jahanamo

[86] So pe: "Emi ko bi yin leere owo-oya kan lori re. Emi ko si si ninu awon onitan-aroso

[87] Ki ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda

[88] Ati pe dajudaju e maa mo iro re (si ododo) laipe

Àwọn Ẹgbẹ́

Surah 39

[1] Isokale Tira naa (sele) lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon

[2] Dajudaju Awa so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. Nitori naa, josin fun Allahu ni olusafomo-esin fun Un

[3] Gbo! Ti Allahu ni esin mimo. Awon ti won si mu awon alafeyinti kan yato si Allahu, (won wi pe): "A o josin fun won bi ko se pe nitori ki won le mu wa sunmo Allahu pekipeki ni." Dajudaju Allahu l’O maa dajo laaarin won nipa ohun ti won n yapa enu nipa re (iyen, esin ’Islam). Dajudaju Allahu ki i fi ona mo eni ti o je opuro, alaigbagbo

[4] Ti o ba je pe Allahu ba fe fi eni kan se omo ni, iba sesa ohun ti O ba fe (fi somo) ninu nnkan ti O da. Mimo ni fun Un (nibi eyi). Oun ni Allahu, Okan soso, Olubori

[5] O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O n ti oru bonu osan. O si n ti osan bonu oru. O si ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. Gbo! Oun ni Alagbara, Alaforijin

[6] O seda yin lati ara emi eyo kan. Leyin naa, O da iyawo re lati ara re. O si so mejo kale fun yin ninu eran-osin ni tako-tabo. O n seda yin sinu iya yin, eda kan leyin eda kan ninu awon okunkun meta. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. TiRe ni ijoba. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo

[7] Ti e ba sai moore, dajudaju Allahu roro lai si eyin (ko si ni bukata si yin). Ko si yonu si aimoore fun awon erusin Re. Ti e ba dupe, O maa yonu si i fun yin. Eleru-ese kan ko si nii ru eru ese elomiiran. Leyin naa, odo Oluwa yin ni ibupadasi yin. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda

[8] Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, o maa pe Oluwa re ni oluseri si odo Re. Leyin naa, nigba ti O ba se idera fun un lati odo Re, o maa gbagbe ohun t’o se ni adua si (Oluwa re) siwaju. O si maa so (awon eda kan) di akegbe fun Allahu nitori ki o le ko isina ba (elomiiran) ni oju ona esin Re (’Islam). So pe: "Fi aigbagbo re jegbadun aye fun igba die. Dajudaju iwo wa ninu awon ero inu Ina

[9] Nje eni ti o je olutele ti Allahu (t’o je) oluforikanle ati oludideduro (lori irun kiki) ni awon akoko ale, t’o n sora fun orun, t’o si n ni agbekele ninu aanu Oluwa re (da bi elese bi?) So pe: "Nje awon ti won nimo ati awon ti ko nimo dogba bi? Awon onilaakaye nikan l’o n lo iranti

[10] So pe: "Eyin erusin Mi ti e gbagbo ni ododo, e beru Oluwa yin. Esan rere wa fun awon t’o se rere ni ile aye yii. Ile Allahu si gbooro. Awon onisuuru ni Won si maa fun ni esan (rere ise) won lai la isiro lo

[11] So pe: "Dajudaju Won pa mi ni ase pe ki ng josin fun Allahu ni ti oluse-afomo-esin fun Un

[12] Won tun pa mi ni ase pe ki emi je eni akoko (ninu) awon musulumi (ni asiko temi)

[13] So pe: "Dajudaju emi n paya iya ojo nla, ti mo ba fi le yapa ase Oluwa mi

[14] So pe: "Allahu ni emi yoo maa josin fun (mo maa je) oluse-afomo-esin mi fun Un

[15] Nitori naa, ki e josin fun ohun ti e ba fe leyin Re." So pe: "Dajudaju awon eni ofo ni awon t’o se emi ara won ati ara ile won lofo ni Ojo Ajinde. Gbo! Iyen, ohun ni ofo ponnbele

[16] Awon aja Ina maa wa ni oke won. Awon aja yo si wa ni isale won. Iyen ni Allahu fi n deru ba awon erusin Re (bayii pe:) "Eyin erusin Mi, e beru Mi

[17] Awon ti won yago fun awon orisa lati josin fun un, won si seri pada si (jijosin fun) Allahu, iro idunnu n be fun won. Nitori naa, fun awon erusin Mi ni iro idunnu

[18] Awon t’o n teti gbo oro, ti won si n tele eyi t’o dara julo ninu re, awon wonyen ni awon ti Allahu fi mona. Awon wonyen, awon ni onilaakaye

[19] Se eni ti oro iya Ina ti kole lori (nipa aigbagbo re, se ko nii wona ni?) Se iwo l’o maa la eni t’o wa ninu Ina (nipase aigbagbo re) ni

[20] Sugbon awon t’o beru Oluwa won, tiwon ni awon ile giga, ti awon ile giga tun wa loke re, awon odo yo si maa san ni isale re. Adehun Allahu ni (eyi). Allahu ko si nii ye adehun naa

[21] Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O so omi kale lati sanmo, O si mu omi naa bo sinu awon opopona odo ninu ile, leyin naa, O n fi mu irugbin ti awo won yato sira won jade, leyin naa, (irugbin naa) yoo gbe, o si maa ri i ni pipon, leyin naa, O maa so o di rirun? Dajudaju iranti wa ninu iyen fun awon onilaakaye

[22] Nje eni ti Allahu gba okan re laaye fun esin ’Islam, ti o si wa ninu imole lati odo Oluwa re (da bi alaigbagbo bi)? Egbe ni fun awon ti okan won le si iranti Allahu. Awon wonyen wa ninu isina ponnbele

[23] Allahu l’O so oro t’o dara julo kale, (o je) Tira, ti (awon oro inu re) jora won ni oro asotunso, ti awo ara awon t’o n paya Oluwa won yo si maa wariri nitori re. Leyin naa, awo ara won ati okan won yoo maa ro nibi iranti Allahu. Iyen ni imona Allahu. O si n fi se imona fun eni ti O ba fe. Eni ti Allahu ba si lona, ko si nii si afinimona kan fun un

[24] Nje eni ti o maa foju ara re ko aburu iya Ina ni Ojo Ajinde (da bi eni ti o maa wo inu Ogba Idera woorowo)? Won yo si so fun awon alabosi pe: "E to iya ohun ti e n se nise wo

[25] Awon t’o siwaju won pe ododo niro. Nitori naa, iya de ba won ni aye ti won ko ti fura

[26] Allahu fun won ni abuku iya to wo ninu isemi aye yii. Iya orun si tobi julo ti o ba je pe won mo

[27] A si ti se gbogbo akawe fun awon eniyan ninu al-Ƙur’an yii nitori ki won le lo iranti

[28] Al-Ƙur’an ni ede Larubawa, eyi ti oro inu re ko doju ru (l’A sokale) nitori ki won le beru (Allahu)

[29] Allahu fi akawe kan lele; erukunrin kan t’o wa labe ase oga pupo ti won n fa a kiri (ko si mo ta ni o maa da lohun ninu awon oga re) ati (akawe) erukunrin kan t’o da wa gedegbe labe ogakunrin kan. Nje awon (eru) mejeeji dogba ni akawe bi? Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ni ko mo

[30] Dajudaju iwo maa ku. Dajudaju awon naa maa ku

[31] Leyin naa, ni Ojo Ajinde dajudaju eyin yoo maa ba ara yin se ariyanjiyan ni odo Oluwa yin

[32] Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o paro mo Allahu, t’o tun pe ododo niro nigba ti o de ba a? Se ki i se Ina ni ibugbe fun awon alaigbagbo ni

[33] Eni ti o si mu ododo wa (iyen, Anabi Muhammad s.a.w.) ati (awon) eni t’o gba a gbo ni ododo; awon wonyen, awon ni oluberu (Allahu)

[34] Ohunkohun ti won ba n fe wa fun won ni odo Oluwa won. Iyen si ni esan awon eni rere

[35] nitori ki Allahu le ba won pa aburu ti won se re ati (nitori) ki O le fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san won ni esan won

[36] Se Allahu ko to fun erusin Re ni? Won si n fi awon elomiiran leyin Re deru ba o! Enikeni ti Allahu ba si lona, ko le si afinimona kan fun un

[37] Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), ko le si asinilona fun un. Se Allahu ko ni Alagbara, Olugba-esan

[38] Dajudaju ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da awon sanmo ati ile?", dajudaju won a wi pe: "Allahu ni." So pe: "E so fun mi nipa awon nnkan ti e n pe leyin Allahu, ti Allahu ba gbero inira kan ro mi, nje won le mu inira Re kuro fun mi? Tabi ti O ba gbero ike kan si mi, nje won le da ike Re duro bi?" So pe: "Allahu to fun mi. Oun si ni awon olugbarale n gbarale

[39] So pe: "Eyin eniyan mi, e se tiyin ni aye yin. Emi naa n se temi. Nitori naa, laipe e maa mo

[40] eni ti iya ti o maa yepere re maa de ba, ti iya gbere si maa ko le lori

[41] Dajudaju Awa so Tira kale fun o pelu ododo (ki o le fi se iranti) fun awon eniyan. Nitori naa, eni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Eni ti o ba si sina, o sina fun emi ara re. Iwo si ko ni oluso lori won

[42] Allahu l’O n gba awon emi ni akoko iku won ati (awon emi) ti ko ku soju oorun won. O n mu (awon emi) ti O ti pebubu iku le lori mole. O si n fi awon yooku sile titi di gbedeke akoko kan. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle

[43] Tabi won mu awon olusipe miiran leyin Allahu ni? So pe: "(Won mu won ni olusipe) t’o si je pe won ko ni agbara kan kan, won ko si nii laakaye

[44] So pe: "Ti Allahu ni gbogbo isipe patapata. TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. Leyin naa, odo Re ni won yoo da yin pada si

[45] Nigba ti won ba daruko Allahu nikan soso, okan awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo maa sa kuro (nibi mimu Allahu ni okan soso). Nigba ti won ba si daruko awon miiran (ti won n josin fun) leyin Re, nigba naa ni won yoo maa dunnu

[46] So pe: "Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile, Onimo-ikoko ati gbangba, Iwo l’O maa dajo laaarin awon erusin Re nipa ohun ti won n yapa enu si

[47] Ti o ba je pe dajudaju gbogbo nnkan ti o wa lori ile je ti awon alabosi ati iru re miiran pelu re (tun je tiwon ni), won iba fi serapada (fun emi ara won) nibi aburu iya ni Ojo Ajinde. (Nigba yen) ohun ti won ko lero maa han si won ni odo Allahu

[48] Awon aburu ohun ti won se nise maa han si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si maa diya t’o maa yi won po

[49] Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, o maa pe Wa. Leyin naa, nigba ti A ba fun un ni idera kan lati odo Wa, o maa wi pe: "Won fun mi pelu imo ni." Ko si ri bee, adanwo ni, sugbon opolopo won ni ko mo

[50] Awon t’o siwaju won kuku wi (iru) re, sugbon ohun ti won n se nise ko ro won loro

[51] Aburu ohun ti won se nise si ba won. Awon alabosi ninu awon wonyi naa, aburu ohun ti won se nise yoo ba won. Won ko si nii mori bo

[52] Se won ko mo pe dajudaju Allahu l’O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo

[53] So pe: "Eyin erusin Mi, ti e ti dese pupo si emi ara yin lorun, e ma se soreti nu nipa ike Allahu. Dajudaju Allahu l’O n saforijin gbogbo ese patapata. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun

[54] E seri pada (ni ti ironupiwada) si odo Oluwa yin. Ki e si juwo-juse sile fun Un siwaju ki iya naa t’o wa ba yin. (Bi bee ko) leyin naa, A o nii ran yin lowo

[55] Ki e si tele ohun ti o dara julo ti won sokale fun yin lati odo Oluwa yin siwaju ki iya naa to wa ba yin ni ojiji, nigba ti eyin ko nii fura

[56] Nitori ki emi kan ma baa wi pe: "Mo ka abamo lori bi mo se jafara lori aitele ase Allahu. Ati pe emi wa ninu awon t’o n fi (oro Re) se yeye

[57] Tabi ki o ma baa wi pe: "Ti o ba je pe Allahu fi ona mo mi ni, dajudaju emi iba wa ninu awon oluberu (Allahu)

[58] Tabi nigba ti o ba ri Ina ki o ma baa wi pe: "Ti o ba je pe ipadasaye wa fun mi ni, emi iba si wa ninu awon oluse-rere

[59] Rara o! Awon ayah Mi kuku ti de ba o. O pe e niro. O tun segberaga. O si wa ninu awon alaigbagbo

[60] Ati pe ni Ojo Ajinde, o maa ri awon t’o paro mo Allahu ti oju won maa dudu. Se inu ina Jahnamo ko ni ibugbe fun awon onigbeeraga ni

[61] Allahu yoo gba awon t’o beru (Re) la sinu ile igbala won (iyen, Ogba Idera). Aburu ko nii fowo ba won. Won ko si nii banuje

[62] Allahu ni Eledaa gbogbo nnkan. Oun si ni Oluso lori gbogbo nnkan

[63] TiRe ni awon kokoro apoti-oro awon sanmo ati ile. Awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, awon wonyen, awon ni eni ofo

[64] So pe: "Se nnkan miiran yato si Allahu l’e n pa mi lase pe ki ng maa josin fun, eyin alaimokan

[65] Dajudaju A ti fi imisi ranse si iwo ati awon t’o siwaju re (pe) "Dajudaju ti o ba sebo, ise re maa baje. Dajudaju o si maa wa ninu awon eni ofo

[66] Rara (ma sebo). Allahu nikan ni ki o josin fun. Ki o si wa ninu awon oludupe (fun Un)

[67] Won ko bu iyi fun Allahu bi o se to lati bu iyi fun Un. Gbogbo ile patapata si ni (Allahu) maa fowo ara Re gbamu ni Ojo Ajinde. O si maa fi owo otun Re ka sanmo korobojo. Mimo ni fun Un. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[68] Won a fon fere oniwo fun iku. Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile si maa ku afi eni ti Allahu ba fe. Leyin naa, won maa fon on ni ee keji, nigba naa won maa wa ni idide. Won yo si maa wo sun

[69] Ati pe ile naa yoo maa tan yanranyanran pelu imole Oluwa re. Won maa gbe iwe ise eda lele. Won si maa mu awon Anabi ati awon elerii wa. A o si sedajo laaarin won pelu ododo. A o si nii sabosi si won

[70] Ati pe Won maa san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n se nise

[71] Won yo si da awon t’o sai gbagbo lo sinu ina Jahnamo nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Nje awon Ojise kan ko wa ba yin lati aarin ara yin, ti won n ke awon ayah Oluwa yin fun yin, ti won si n kilo ipade ojo yin oni yii fun yin?" Won wi pe: "Rara (won wa ba wa)." Sugbon oro iya ko le awon alaigbagbo lori ni

[72] A oo so pe: "E wo enu ona ina Jahnamo. Olusegbere (ni yin) ninu re. Ibugbe awon olusegberaga si buru

[73] Ati pe A oo ko awon t’o beru Oluwa won lo sinu Ogba Idera nijonijo, titi di igba ti won ba de ibe, won maa si awon ilekun re sile (fun won). Awon eso re yo si so fun won pe: "Ki alaafia maa ba yin. Eyin se ise t’o dara. Nitori naa, e wo inu Ogba Idera, (ki e di) olusegbere (ninu re)

[74] Won a so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O mu adehun Re se fun wa. O tun jogun ile naa fun wa, ti a n gbe nibikibi ti a ba fe ninu Ogba Idera." Esan awon oluse-rere ma si dara

[75] O maa si ri awon Molaika ti won n rokirika ni egbe Ite-ola. Won n se afomo ati idupe fun Oluwa won. A maa fi ododo sedajo laaarin awon eda. Won si maa so pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

Olùdáríjì

Surah 40

[1] Ha mim

[2] Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Onimo

[3] Alaforijin-ese, Olugba-ironupiwada, Eni lile nibi iya, Olore, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Odo Re ni abo eda

[4] Ko si eni ti o maa se atako si awon ayah Allahu afi awon t’o sai gbagbo. Nitori naa, ma se je ki igbokegbodo won ninu ilu ko etan ba o

[5] Ijo (Anabi) Nuh pe ododo niro siwaju won. Awon ijo (miiran) leyin won (naa se bee). Ijo kookan lo gbero lati ki Ojise won mole. Won fi iro ja ododo niyan nitori ki won le fi wo ododo lule. Mo si gba won mu. Nitori naa, bawo ni iya (ti mo fi je won) ti ri (lara won na)

[6] Ati pe bayen ni oro Oluwa re se ko lori awon t’o sai gbagbo pe: "Dajudaju awon ni ero inu Ina

[7] Awon t’o gbe Ite-ola naa ru ati awon t’o wa ni ayika re, won n se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won gba Allahu gbo. Won si n toro aforijin fun awon t’o gbagbo ni ododo (bayii pe): "Oluwa wa, ike ati imo (Re) gbooro ju gbogbo nnkan lo, nitori naa, saforijin fun awon t’o ronu piwada, ti won si tele oju-ona Re. Ki O si so won ninu iya ina Jehim

[8] Oluwa wa, fi won sinu awon Ogba Idera ti O se ni adehun fun awon ati eni t’o se ise rere ninu awon baba won, awon aya won ati awon aromodomo won. Dajudaju Iwo ni Alagbara, Ologbon

[9] So won ninu awon aburu. Enikeni ti O ba so nibi awon aburu (iya) ni ojo yen, dajudaju O ti ke e. Iyen si ni erenje nla

[10] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, won yoo pe won (lati so fun won ninu Ina pe): " Dajudaju ibinu ti Allahu tobi ju ibinu ti e n bi sira yin (ninu Ina, sebi) nigba ti won n pe yin sibi igbagbo ododo, nse ni e n sai gbagbo

[11] Won wi pe: "Oluwa wa, O pa wa ni ee meji. O si ji wa ni ee meji. Nitori naa, a si jewo awon ese wa. Nje ona kan wa lati jade (pada si ile aye) bi

[12] (E wa ninu Ina) yen nitori pe dajudaju nigba ti won ba pe Allahu nikan soso, eyin sai gbagbo. Nigba ti won ba sebo si I, e si maa gbagbo (ninu ebo). Nitori naa, idajo n je ti Allahu, O ga, O tobi

[13] Oun ni Eni t’O n fi awon ami Re han yin. O si n so arisiki kale fun yin lati sanmo. Ko si eni t’o n lo iranti afi eni t’o n seri pada si odo Allahu (nipase ironupiwada)

[14] Nitori naa, e pe Allahu ni ti olusafomo-esin fun Un, awon alaigbagbo ibaa korira Re

[15] (Allahu) Eni t’O ni gbogbo ipo ajulo, Oluwa Ite-ola, O n fi imisi (al-Ƙur’an) ranse pelu ase Re si eni ti O fe ninu awon erusin Re nitori ki o le fi sekilo nipa Ojo ipade naa

[16] Ni ojo ti won yoo yo jade (lati inu saree), kini kan ko si nii pamo nipa won fun Allahu. (Allahu yo si so pe): "Ti ta ni ijoba ni ojo oni? Ti Allahu, Okan soso, Olubori ni

[17] Ni oni ni A oo san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. Ko si si abosi kan ni oni. Dajudaju Allahu ni Oluyara nibi isiro-ise

[18] Ati pe sekilo ojo ti o sunmo fun won. Nigba ti awon okan ba ga de gogongo, ti o maa kun fun ibanuje, ko nii si ore imule ati olusipe kan ti won maa tele oro re lori (oro) awon alabosi

[19] (Allahu) mo oju ijanba ati ohun ti awon okan fi pamo

[20] Ati pe Allahu l’O maa fi ododo dajo. Awon ti won n pe leyin Re, won ko le se idajo kan kan. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran

[21] Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won ni agbara ju won lo. Won si lo ile (fun oko dida ju won lo). Sibesibe Allahu mu won nitori ese won. Ko si si oluso kan fun won (nibi iya) Allahu

[22] Iyen nitori pe awon Ojise won n wa ba won pelu awon eri t’o yanju, sugbon won sai gbagbo. Nitori naa, Allahu mu won. Dajudaju Oun ni Alagbara, Eni lile nibi iya

[23] Dajudaju A fi awon ami Wa ati eri t’o yanju ran (Anabi) Musa nise

[24] si Fir‘aon, Hamon ati Ƙorun. Sugbon won wi pe: "Opidan, opuro ni (Anabi Musa)

[25] Nigba ti o mu ododo naa de odo won lati odo Wa, won wi pe: "E pa awon omokunrin awon t’o gbagbo pelu re, ki e si fi awon omobinrin won sile." Ete awon alaigbagbo ko si ninu kini kan bi ko se ninu ofo

[26] Fir‘aon wi pe: "E fi mi sile ki ng pa Musa, ki o si pe Oluwa re (wo boya O maa gba a sile). Dajudaju emi n beru pe o maa yi esin yin pada tabi pe o maa safi han ibaje lori ile

[27] (Anabi) Musa so pe: "Dajudaju emi sa di Oluwa mi ati Oluwa yin kuro lowo gbogbo onigbeeraga, ti ko gba Ojo isiro-ise gbo

[28] Okunrin onigbagbo ododo kan t’o n fi igbagbo re pamo ninu awon eniyan Fir‘aon so pe: "Se e maa pa okunrin kan nitori pe o n so pe, ‘Allahu ni Oluwa mi.’ O si kuku ti mu awon eri t’o yanju wa ba yin lati odo Oluwa yin. Ti o ba je opuro, (iya) iro re wa lori re. Ti o ba si je olododo, apa kan eyi ti o se ni ileri fun yin yo si ko le yin lori. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo eni ti o je alaseju, opuro

[29] Eyin eniyan mi, eyin l’e ni ijoba lonii, eyin si ni alase lori ile naa. Sugbon ta ni o maa ran wa lowo ti iya Allahu ba de ba wa?" Fir‘aon wi pe: "Emi ko fi nnkan kan han yin bi ko se ohun ti mo ri (ninu oye mi). Emi ko si to yin si ona kan bi ko se oju ona imona

[30] Eni t’o gbagbo ni ododo tun so pe: "Eyin eniyan mi, dajudaju iru ojo (esan iya t’o sele si) awon omo-ogun onijo ni emi n paya lori yin

[31] Iru ise (iparun t’o sele si awon) eniyan Nuh, ‘Ad, Thamud ati awon t’o tele won. Allahu ko si gbero abosi si awon erusin naa

[32] Eyin eniyan mi, dajudaju emi n paya Ojo ipe fun yin

[33] Ojo ti e maa peyinda lati sa lo; ko si nii si alaabo kan fun yin lodo Allahu. Ati pe eni ti Allahu ba si lona, ko le si afinimona kan fun un

[34] Ati pe dajudaju (Anabi) Yusuf ti to yin wa siwaju pelu awon alaye oro t’o yanju, sugbon eyin ko ye wa ninu iyemeji nipa ohun ti o mu wa ba yin titi di igba ti o fi ku, ti e fi wi pe: "Allahu ko nii gbe Ojise kan dide mo leyin re." Bayen ni Allahu se n so eni ti o je alaseju, oniyemeji nu

[35] Awon t’o n jiyan nipa awon ayah Allahu laisi eri kan ti o de ba won. Ese nla si ni ni odo Allahu ati ni odo awon t’o gbagbo ni ododo. Bayen ni Allahu se n fi edidi bo gbogbo okan onigbeeraga, ajeninipa.”

[36] Fir‘aon wi pe: "Hamon, mo ile giga fiofio kan fun mi nitori ki emi le de awon oju ona naa

[37] Awon oju ona (inu) sanmo ni, nitori ki emi le yoju wo Olohun Musa nitori pe dajudaju emi n ro o si opuro." Bayen ni won se ise aburu (owo) Fir‘aon ni oso fun un. Won si seri re kuro loju ona (esin Allahu). Ete Fir‘aon ko si wa ninu kini kan bi ko se ninu ofo

[38] Eni t’o gbagbo ni ododo tun so pe: "Eyin eniyan mi, e tele mi, mo maa juwe yin si oju ona imona

[39] Eyin eniyan mi, isemi ile aye yii je igbadun lasan. Dajudaju orun si ni ile gbere

[40] Eni ti o ba se aburu kan, Won ko nii san an ni esan kan ayafi iru re. Eni ti o ba si se ise rere ni okunrin tabi ni obinrin, ti o si je onigbagbo ododo, awon wonyen ni won maa wo inu Ogba Idera. Won yoo maa pese arisiki fun won ninu re lai la isiro lo

[41] Eyin eniyan mi, ki lo mu yin ti mo n pe yin sibi igbala, ti eyin si n pe mi sibi Ina

[42] E n pe mi pe ki ng sai gbagbo ninu Allahu, ki ng si so nnkan ti emi ko nimo nipa re di akegbe fun Un. Emi si n pe yin si odo Alagbara, Alaforijin

[43] Laisi tabi-sugbon, dajudaju nnkan ti e n pe mi si, ko ni eto si ipe kan ni aye ati ni orun. Ati pe dajudaju odo Allahu ni abo wa. Dajudaju awon olutayo-enu-ala, awon ni ero inu Ina

[44] Nitori naa, e maa ranti ohun ti mo n so fun yin. Mo si n fi oro mi ti si odo Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa awon erusin

[45] Allahu si so o nibi awon aburu ti won dete re. Iya buruku si yi awon eniyan Fir‘aon po

[46] Ina ni Won yoo maa seri won si ni owuro ati ni asale. Ati pe ni ojo ti Akoko naa ba de (A maa so pe): "E mu awon eniyan Fir‘aon wo inu iya Ina t’o le julo

[47] (Ranti) nigba ti won ba n ba ara won se ariyanjiyan ninu Ina. Awon ole yoo wi fun awon ti won segberaga pe: “Dajudaju awa je omoleyin fun yin, nje eyin le gbe ipin kan kuro fun wa ninu iya Ina?”

[48] Awon t’o segberaga wi pe: "Dajudaju gbogbo wa l’a wa ninu re.” Dajudaju Allahu kuku ti dajo laaarin awon eru naa

[49] Awon t’o wa ninu Ina tun wi fun awon eso-Ina pe: "E ba wa pe Oluwa yin, ki O se iya ni fifuye fun wa fun ojo kan

[50] Won yoo so pe: "Nje awon Ojise yin ki i mu awon eri t’o yanju wa ba yin bi?" Won wi pe: “Rara, (won n mu un wa).” Won so pe: “E sadua wo.” Adua awon alaigbagbo ko si je kini kan bi ko se sinu isina. ona wo ni awon alaigbagbo n gba ri oore laye? Ko si oore aye kan ti o le te alaigbagbo lowo bi ko se ipin re ninu kadara. Amo ni ti onigbagbo ododo oore inu kadara ati oore adua l’o wa fun un niwon igba ti adua re ba ti ba sunnah Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) mu

[51] Dajudaju Awa kuku maa saranse fun awon Ojise Wa ati awon t’o gbagbo ni ododo ninu igbesi aye yii ati ni ojo ti awon elerii yo dide (ni Ojo Ajinde)

[52] Ni ojo ti awawi awon alabosi ko nii se won ni anfaani; egun n be fun won, ile (iya) buruku si wa fun won

[53] Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni imona. A si jogun Tira fun awon omo ’Isro’il

[54] (O je) imona ati iranti fun awon onilaakaye

[55] Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Toro aforijin fun ese re. Ki o si se afomo pelu idupe fun Oluwa re ni asale ati ni owuro kutukutu. awon ti Anabi Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) tu sile wonyi awon ni olori awon osebo ninu ilu Mokkah. Won si ti pa awon musulumi kan nipakupa siwaju ki owo to te awon naa loju ogun Badr. Amo ohun ti Anabi Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) ro t’o fi tu won sile ni pe ‘O gba iyawo lowo omo re o si fi saya!’. Oro ko si ri bee nitori pe a o gbodo foju bin-intin wo eyikeyii asise tabi ese. A gbodo kun fun titoro aforijin ni lodo Allahu Alaforijin. Ko si ohun t’o dara to riri aforijin gba lodo Allahu lori gbogbo asise wa siwaju ojo iku wa

[56] Dajudaju awon t’o n jiyan nipa awon ayah Allahu laini eri kan (lowo) ti o wa ba won (lati odo Allahu), ko si kini kan ninu igba-aya won ayafi okan-giga. Won ko si le de ibi giga (pelu okan giga). Nitori naa, sa di Allahu. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran

[57] Dajudaju iseda awon sanmo ati ile tobi ju iseda awon eniyan; sugbon opolopo awon eniyan ni ko mo

[58] Afoju ati oluriran ko dogba. Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere ati onise-aburu (ko dogba). Die l’e n lo ninu iranti

[59] Dajudaju Akoko naa n bo, ko si si iyemeji ninu re. Sugbon opolopo awon eniyan ni ko gbagbo

[60] Oluwa yin so pe: "E pe Mi, ki Ng jepe yin. Dajudaju awon t’o n segberaga nipa jijosin fun Mi, won yoo wo inu ina Jahanamo ni eni yepere

[61] Allahu ni Eni ti O se oru fun yin nitori ki e le sinmi ninu re. (O si se) osan (nitori ki e le fi) riran. Dajudaju Allahu ni Olola-julo lori awon eniyan, sugbon opolopo awon eniyan ki i dupe (fun Un)

[62] Iyen ni Allahu, Oluwa yin, Eledaa gbogbo nnkan. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo

[63] Bayen naa ni won se n se awon t’o n tako awon ayah Allahu lori kuro nibi ododo (siwaju tiwon)

[64] Allahu ni Eni ti O se ile fun yin ni ibugbe. O mo sanmo (le yin lori). O ya aworan yin. O si ya aworan yin daradara. O pese arisiki fun yin ninu awon nnkan daadaa. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, mimo ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda

[65] Oun ni Alaaye. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, e pe E ni ti olusafomo-esin fun Un. Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda

[66] So pe: "Dajudaju Won ko fun mi pe ki ng josin fun awon ti e n pe leyin Allahu, nigba ti awon eri t’o yanju ti de ba mi lati odo Oluwa mi, ti won si pa mi ni ase pe ki ng juwo juse sile (ki ng je musulumi) fun Oluwa gbogbo eda

[67] Oun ni Eni ti O seda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa O mu yin jade ni oponlo. Leyin naa, (O da yin si) nitori ki e le sanngun dopin agbara yin. Leyin naa (O tun da yin si) nitori ki e le di agbalagba. O wa ninu yin eni ti A oo ti gba emi re siwaju (ipo agba). Ati pe (O da yin si) nitori ki e le dagba de gbedeke akoko kan ati nitori ki e le se laakaye

[68] Oun ni Eni ti n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Nigba ti O ba si pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee

[69] Se o o ri awon ti n sariyanjiyan nipa awon ayah Allahu bi won se n seri won kuro nibi ododo

[70] Awon t’o pe Tira naa ati ohun ti A fi ran awon Ojise Wa niro, laipe won maa mo

[71] Nigba ti awon sekeseke ati ewon ba wa ni orun won, ti won yoo fi maa wo won

[72] sinu omi gbigbona. Leyin naa, won yoo fi won ko Ina

[73] Leyin naa, Won maa so fun won pe: "Ibo ni ohun ti e so di orisa wa

[74] (Ohun ti e josin fun) leyin Allahu (da)?" Won a wi pe: "Won ti di ofo mo wa lowo. Bee tie ko, awa ki i pe nnkan kan teletele." Bayen ni Allahu se n si awon alaigbagbo lona

[75] Iyen nitori pe e n yo lori ile lai letoo ati nitori pe e n se faari (lori aigbagbo)

[76] E wo awon enu ona ina Jahanamo; olusegbere ni won ninu re. O si buru ni ibugbe fun awon onigbeeraga

[77] Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. O see se ki A fi apa kan eyi ti A se ni ileri fun won han o tabi ki A ti gba emi re (siwaju asiko naa). Odo Wa kuku ni won maa da won pada si

[78] Ati pe A kuku ti ran awon Ojise nise siwaju re. Awon ti A so itan won fun o wa ninu won. Awon ti A o si so itan won fun o wa ninu won. Ati pe ko to fun Ojise kan lati mu ami kan wa afi pelu iyonda Allahu. Nigba ti ase Allahu ba si de, A maa fi ododo dajo. Awon opuro si maa sofo danu nibe yen

[79] Allahu ni Eni ti O da awon eran-osin fun yin nitori ki e le maa gun ninu won. E o si maa je ninu won

[80] Awon anfaani (miiran) wa fun yin lara eran-osin. Ati nitori ki e le de ona jijin t’o wa lokan yin lori (gigun) won (kiri). E o si maa fi awon (eran-osin) ati oko oju-omi gbe awon eru

[81] (Allahu) n fi awon ami Re han yin. Nitori naa, ewo ninu awon ami Allahu l’e maa tako

[82] Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won po (ni onka) ju won lo. Won ni agbara ju won lo. Won si lo ile (fun oko dida ju won lo). Sibesibe ohun ti won n se nise ko ro won loro (nibi iya)

[83] Nigba ti awon Ojise mu awon eri t’o yanju wa ba won, won yo ayoporo nitori ohun t’o wa lodo won ninu imo (aye). Ohun ti won si n fi se yeye si diya t’o yi won po

[84] Nigba ti won ri iya Wa, won wi pe: "A gbagbo ninu Allahu, Oun nikan soso. A si lodi si nnkan ti a so di akegbe fun Un

[85] Igbagbo won ko se won ni anfaani nigba ti won ri iya Wa. Ise Allahu, eyi ti o ti sele siwaju si awon eru Re (ni eyi). Awon alaigbagbo si sofo danu nibe yen

Tí a ṣàlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́

Surah 41

[1] Ha mim

[2] Isokale imisi kan (niyi) lati odo Ajoke-aye, Asake-orun

[3] (Eyi ni) Tira kan ti Won salaye awon ayah inu re; al-Ƙur’an ni ede Larubawa ni fun ijo t’o nimo

[4] (O je) iro-idunnu ati ikilo, sugbon opolopo won gbunri kuro nibe. Won ko si teti si i

[5] Won si wi pe: "Okan wa wa ni titi pa si ohun ti e n pe wa si. Edidi si wa ninu eti wa. Ati pe gaga wa laaarin awa ati iwo. Nitori naa, maa se tire. Dajudaju awa naa n se tiwa

[6] So pe: "Abara bi iru yin kuku ni emi naa. Won n fi imisi ranse si mi ni, pe Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Nitori naa, e duro sinsin ti I, ki e si toro aforijin ni odo Re. Egbe si ni fun awon osebo

[7] awon ti ko yo Zakah. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin

[8] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, esan ti ko nii pedin n be fun won

[9] So pe: "Se dajudaju eyin maa sai gbagbo ninu Eni ti O seda ile fun ojo meji, e si n so (eda Re) di akegbe fun Un?" Iyen si ni Oluwa gbogbo eda

[10] O si fi awon apata sinu ile lati oke re. O fi ibukun sinu re. O si pebubu awon arisiki (ati ohun amusoro) sinu re laaarin ojo merin. (Awon ojo naa) dogba (sira won) fun awon olubeere (nipa re). o jeyo ninu won pe “Allahu seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa.” O wa bee ninu surah al-’A‘rof; 7:54 nnkan naa ko nii dohun afi pelu gbolohun “kunfayakun”. Awon eda ti ko ba si jemo eroja iseda tabi awon eda ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) ko so nipa eroja iseda won fun wa Allahu l’O kuku nimo nipa iseda awon eda Re awon eda kan di eda pelu gbolohun “kunfayakun” nikan. Awon eda kan si di eda nipase eroja iseda ati gbolohun “kunfayakun”. Allahu n seda ohun ti O ba fe ni ona ti O ba fe. Nitori naa gbolohun “kunfayakun” t’o je ti Allahu nikan soso ko le so Allahu di olukanju. Ikanju ki i se iroyin rere fun Allahu. Bi Allahu se gbaroyin pelu gbolohun “kunfayakun”

[11] Leyin naa, Allahu wa ni oke sanmo, nigba ti sanmo wa ni eefin. O si so fun ohun ati ile pe: "E wa bi e fe tabi e ko." Awon mejeeji so pe: "A wa pelu ifinnu-findo

[12] O si pari (iseda) re si sanmo meje fun ojo meji. O si fi ise sanmo kookan ranse sinu re. A si fi awon atupa (irawo) se sanmo ile aye ni oso ati aabo (fun un). Iyen ni eto Alagbara, Onimo

[13] Ti won ba gbunri, so pe: "Emi n sekilo iparun iru iparun ijo ‘Ad ati Thamud fun yin ni

[14] Nigba ti awon Ojise won wa ba won niwaju won ati leyin won, (won so) pe: "Eyin ko gbodo josin fun eni kan afi Allahu." Won wi pe: "Ti o ba je pe Oluwa wa ba fe ni, iba so molaika kale (fun ipepe yii). Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise

[15] Ni ti ijo ‘Ad, won segberaga ni ori ile lai letoo. Won si wi pe: "Ta ni o lagbara ju wa lo na?" Se won ko ri i pe dajudaju Allahu ti O seda won, O ni agbara ju won lo ni. Won si n se atako si awon ayah Wa

[16] Nitori naa, A ran ategun lile si won ni awon ojo buruku kan nitori ki A le je ki won to iya yepere wo ninu isemi aye yii. Iya ojo Ikeyin si maa yepere won julo; Won ko si nii ran won lowo. “ojo kan” di “awon ojo kan” ninu ayah ti surah Fussilat. Amo apapo onka ojo iparun won l’o jeyo ninu ayah ti surah al-Haƙƙoh. Se e ti ri i bayii pe ainimo nipa eto laaarin awon ayah le sokunfa itakora ayah loju alaimokan

[17] Ni ti ijo Thamud, A salaye imona fun won, sugbon won nifee si airiran dipo imona. Nitori naa, igbe iya ti i yepere eda gba won mu nitori ohun ti won n se nise

[18] A si gba awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n beru (Allahu) la

[19] Ni ojo ti won maa ko awon ota Allahu jo sibi Ina, won yo si ko awon eni akoko won papo mo awon eni ikeyin won

[20] titi di igba ti won ba de ibe tan, igboro won, iriran won ati awo ara won yo si maa jerii le won lori nipa ohun ti won n se nise

[21] Won yoo wi fun awo ara won pe: "Nitori ki ni e se jerii le wa lori na?" Won yoo so pe: "Allahu, Eni ti O fun gbogbo nnkan ni oro so, Oun l’O fun wa ni oro so. Oun si l’O seda yin nigba akoko. Odo Re si ni won yoo da yin pada si

[22] Eyin ko le para yin mo (kuro nibi ese, nitori) ki igboro yin, iriran yin ati awo ara yin ma fi le jerii le yin lori. Sugbon e lero pe dajudaju Allahu ko mo opolopo ninu ohun ti e n se nise

[23] Iyen, ero yin ti e lero si Oluwa yin lo ko iparun ba yin. E si di eni ofo

[24] Ti won ba se suuru (fun iya), Ina kuku ni ibugbe fun won. Ti won ba si fe seri pada si sise ohun ti Allahu yonu si (ni asiko yii), A o nii gba won laye lati seri pada

[25] Awa ti yan awon alabaarin kan fun won, ti won se ohun ti n be niwaju won ati ohun ti n be ni eyin won ni oso fun won. Oro naa si ko le won lori (bi o se sele) si awon ijo t’o siwaju won ninu awon alujannu ati eniyan pe dajudaju won je eni ofo

[26] Awon t’o sai gbagbo wi pe: "E ma se teti si al-Ƙur’an yii. Ki e si so isokuso nipa re ki e le bori

[27] Nitori naa, dajudaju A oo fun awon t’o sai gbagbo niya lile to wo. Ati pe dajudaju A oo fi eyi t’o buru ju eyi ti won n se nise san won ni esan

[28] Ina, iyen ni esan awon ota Allahu. Ile gbere wa ninu re fun won. O je esan nitori pe won n tako awon ayah Wa

[29] Awon t’o sai gbagbo wi pe: "Oluwa wa, fi awon mejeeji ti won si wa lona ninu awon alujannu ati eniyan han wa nitori ki a le fi awon mejeeji si abe gigise wa, nitori ki won le wa ni isale patapata

[30] Dajudaju awon t’o so pe: "Allahu ni Oluwa wa." leyin naa, ti won duro sinsin, awon molaika yoo maa sokale wa ba won (ni ojo iku won, won si maa so pe: “E ma se paya, e ma se banuje. Ki e si dunnu si Ogba Idera eyi ti Won n se ni adehun fun yin)

[31] Awa ni ore yin ninu isemi aye ati ni orun. Ohun ti emi yin n fe ti wa fun yin ninu Ogba Idera. Ohun ti e n beere fun si ti wa ninu re

[32] Nnkan igbalejo ni lati odo Alaforijin, Asake-orun.”

[33] Ta ni o dara julo ni oro siso t’o tayo eni ti o pepe si odo Allahu, ti o se ise rere, ti o si so pe: "Dajudaju emi wa ninu awon musulumi

[34] Rere ati aburu ko dogba. Fi eyi ti o dara julo dena (aburu). Nigba naa ni eni ti ota wa laaarin iwo ati oun maa da bi ore alasun-unmo pekipeki

[35] A o nii fun eni kan ni (iwa rere yii) afi awon t’o se suuru. A o nii fun eni kan se afi olori-ire nla

[36] Ati pe ti erokero kan lati odo Esu ba fe se o lori (kuro nibi iwa rere yii), sa di Allahu. Dajudaju Oun ni Olugbo, Onimo

[37] Ninu awon ami Re ni oru, osan, oorun ati osupa. E o gbodo fori kanle fun oorun ati osupa. E fori kanle fun Allahu, Eni ti O da won, ti eyin ba je eni t’o n josin fun Oun nikan soso

[38] Ti won ba si segberaga, awon t’o wa ni odo Oluwa re, won n safomo fun Un ni ale ati ni osan; won ko si kagara

[39] Ninu awon ami Re tun ni pe dajudaju iwo yoo ri ile ni asale. Nigba ti A ba si so omi kale le e lori, o maa rura wa, o si maa ga (fun hihu irugbin jade). Dajudaju Eni ti O ji i, Oun ma ni Eni ti O maa so awon oku di alaaye. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[40] Dajudaju awon t’o n ye awon ayah Wa (sibi omiran), won ko pamo fun Wa. Se eni ti won maa ju sinu Ina l’o loore julo ni tabi eni ti o maa wa ni olufayabale ni Ojo Ajinde? E maa se ohun ti e ba fe. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[41] Dajudaju awon t’o sai gbagbo ninu Tira Iranti naa (iyen, al-Ƙur’an) nigba ti o de ba won (eni iparun ni won.) Dajudaju ohun ma ni Tira t’o lagbara

[42] Ibaje ko nii kan an lati iwaju re ati lati eyin re. Imisi ti won sokale ni lati odo Ologbon, Eleyin

[43] Won ko so oro kan si o bi ko se ohun ti won ti so si awon Ojise t’o siwaju re. Dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, O si ni iya eleta-elero (lodo)

[44] Ti o ba je pe A se al-Ƙur’an ni nnkan kike ni ede miiran yato si ede Larubawa ni, won iba wi pe: "Ki ni ko je ki Won se alaye awon ayah re?" Bawo ni al-Ƙur’an se le je ede miiran (yato si ede Larubawa), nigba ti Anabi (Muhammad s.a.w.) je Larubawa? So pe: "O je imona ati iwosan fun awon t’o gbagbo ni ododo. Awon ti ko si gbagbo, edidi wa ninu eti won. Fojunfoju si wa ninu oju won si (ododo al-Ƙur’an). Awon wonyen ni won si n pe (sibi ododo al-Ƙur’an) lati aye t’o jinna

[45] A kuku fun (Anabi) Musa ni Tira. Won si yapa enu si i. Ti ko ba je pe oro kan ti o ti siwaju ni odo Oluwa re ni, A iba se idajo laaarin won. Dajudaju won tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa al-Ƙur’an

[46] Enikeni ti o ba se ise rere, o se e fun emi ara re. Enikeni ti o ba si se aburu, o se e fun emi ara re. Oluwa re ko si nii se abosi si awon erusin

[47] Odo Re ni won yoo maa da imo Akoko naa pada si. Ko si eso kan ti o maa jade ninu apo re, obinrin kan ko si nii loyun, ko si nii bimo afi pelu imo Re. (Ranti) ojo ti O si maa pe won pe: "Ibo ni awon akegbe Mi (ti e josin fun) wa?" Won a wi pe: "Awa n je ki O mo pe ko si olujerii kan ninu wa (ti o maa jerii pe O ni akegbe)

[48] Ohun ti won n pe teletele si dofo mo won lowo. Won si mo ni amodaju pe ko si ibusasi kan fun awon

[49] Eniyan ko ko susu nibi adua (lati toro) oore. Ti aburu ba si fowo ba a, o maa di olusoretinu, olujakanmuna

[50] Dajudaju ti A ba se idera fun un lati odo Wa leyin aburu ti o fowo ba a, dajudaju o maa wi pe: "Eyi ni temi. Emi ko si ni amodaju pe Akoko naa maa sele. Ati pe dajudaju ti Won ba da mi pada si odo Oluwa mi, dajudaju rere tun wa fun mi ni odo Re." Dajudaju Awa yoo fun awon t’o sai gbagbo ni iro ohun ti won se nise. Dajudaju A si maa fun won ni iya t’o nipon to wo

[51] Ati pe nigba ti A ba se idera fun eniyan, o maa gbunri (kuro ni odo Wa). O si maa segberaga. Nigba ti aburu ba si fowo ba a, nigba naa l’o maa di aladuaa regede

[52] So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe al-Ƙur’an wa lati odo Allahu, leyin naa ti e sai gbagbo ninu re (se eyin ko ti wa ninu iyapa bi?)" Ta l’o sina ju eni ti o wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo)

[53] A oo maa fi awon ami Wa han won ninu ofurufu ati ninu emi ara won titi o maa fi han kedere si won pe dajudaju al-Ƙur’an ni ododo. Nje Oluwa re ko to ki o je pe dajudaju Oun ni Arinu-rode lori gbogbo nnkan

[54] Gbo, dajudaju won wa ninu iyemeji nipa ipade Oluwa won. Gbo, dajudaju Allahu yi gbogbo nnkan ka

Ìmọ̀ràn

Surah 42

[1] Ha mim

[2] ‘Aen sin ƙof

[3] Bayen ni Allahu, Alagbara, Ologbon se n fi imisi ranse si iwo ati awon t’o siwaju re

[4] TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. O ga, O tobi

[5] Sanmo fee faya lati oke won (nipa titobi Allahu). Awon molaika si n se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won si n toro aforijin fun awon t’o wa lori ile. Gbo Mi, dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun

[6] Awon t’o mu awon alatileyin kan leyin Re, Allahu si ni Alaabo lori won. Iwo si ko ni oluso lori won

[7] Bayen ni A se fi al-Ƙur’an ranse si o ni ede Larubawa nitori ki o le fi se ikilo fun ’Ummul-Ƙuro (iyen, ara ilu Mokkah) ati enikeni ti o ba wa ni ayika re (iyen, ara ilu yooku), ati nitori ki o le fi se ikilo nipa Ojo Akojo, ti ko si iyemeji ninu re. Ijo kan yoo wa ninu Ogba Idera. Ijo kan yo si wa ninu Ina t’o n jo

[8] Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se won ni ijo elesin eyo kan. Sugbon O n fi eni ti O ba fe sinu ike Re. Awon alabosi, ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won

[9] Se won mu awon alaabo kan leyin Re ni? Allahu, Oun si ni Alaabo. Oun l’O n so awon oku di alaaye. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[10] Ohunkohun ti e ba yapa enu nipa re, idajo re di odo Allahu. Iyen ni Allahu, Oluwa mi. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni mo maa seri pada si (ni ti ironupiwada). oro Allahu ati idajo Re. Pelu agboye yii ayah yii je okan ninu awon ayah t’o n pa wa lase lati fi al-Ƙur’an ati sunnah Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) yanju awon oro iyapa-enu

[11] (Oun ni) Olupileda awon sanmo ati ile. O seda awon obinrin fun yin lati ara yin. O tun seda awon abo eran-osin lati ara awon ako eran-osin. O n mu yin po si i (nipa iseda yin ni ako-abo). Ko si kini kan bi iru Re. Oun si ni Olugbo, Oluriran

[12] TiRe ni awon kokoro apoti-oro awon sanmo ati ile. O n te arisiki sile fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun elomiiran). Dajudaju Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[13] (Allahu) se ni ofin fun yin ninu esin (’Islam) ohun ti O pa ni ase fun (Anabi) Nuh ati eyi ti O fi ranse si o, ati ohun ti A pa lase fun (Anabi) ’Ibrohim, (Anabi) Musa ati (Anabi) ‘Isa pe ki e gbe esin naa duro. Ki e si ma se pin si ijo otooto ninu re. Wahala l’o je fun awon osebo nipa nnkan ti o n pe won si (nibi mimu Allahu ni okan soso). Allahu l’O n sesa eni ti O ba fe sinu esin Re (ti o n pe won si). O si n fi ona mo eni ti o ba n seri pada si odo Re (nipase ironupiwada)

[14] (Awon osebo) ko si pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Ti ko ba je pe oro kan ti siwaju lodo Oluwa re (pe Oun yoo lo won lara) titi di gbedeke akoko kan ni, Won iba ti dajo laaarin won. Dajudaju awon ti A jogun Tira fun leyin won si tun wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa ’Islam

[15] Nitori iyen, pepe (sinu ’Islam), ki o si duro sinsin gege bi Won se pa o lase. Ma si se tele ife-inu won. Ki o si so pe: "Mo gbagbo ninu eyikeyii Tira ti Allahu sokale. Won si pa mi lase pe ki ng se deede laaarin yin. Allahu ni Oluwa wa ati Oluwa yin. Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Ko si ija laaarin awa ati eyin. Allahu l’O si maa ko wa jo papo. Odo Re si ni abo eda.”

[16] Awon t’o n ba (Anabi s.a.w.) ja nipa (esin) Allahu leyin igba ti awon eniyan ti gba fun un, eri won maa wo lodo Oluwa won. Ibinu n be lori won. Iya lile si wa fun won

[17] Allahu ni Eni ti O so Tira (al-Ƙur’an) ati (ofin) osuwon (deede) kale pelu ododo. Ati pe ki l’o maa fi mo o pe o see se ki Akoko naa ti sunmo

[18] Awon ti ko gba a gbo n wa a pelu ikanju. Awon t’o si gbagbo ni ododo n paya re. Won si mo pe dajudaju ododo ni. Kiye si i, dajudaju awon t’o n jiyan nipa Akoko naa ti wa ninu isina t’o jinna

[19] Allahu ni Alaaanu fun awon erusin Re. O n se arisiki fun eni ti O ba fe. Oun si ni Alagbara, Abiyi

[20] Enikeni ti o ba gbero lati gba eso (ise re ni) orun, A maa se alekun si eso re fun un. Enikeni ti o ba si gbero lati gba eso (ise re ni) aye, A maa fun un ninu re. Ko si nii si ipin kan kan fun un mo ni orun

[21] Tabi won ni awon orisa kan t’o sofin (iborisa) fun won ninu esin, eyi ti Allahu ko yonda re? Ti ko ba je ti oro asoyan (pe A o nii kanju je won niya), Awa iba ti mu idajo wa laaarin won. Dajudaju awon alabosi, iya eleta-elero si wa fun won

[22] O maa ri awon alabosi ti won yoo maa paya nitori ohun ti won se nise, ti o si maa ko le won lori. Awon t’o si gbagbo ni ododo, ti won se ise rere maa wa ni awon aye t’o rewa julo ninu Ogba Idera. Ohun ti won ba n fe maa wa fun won ni odo Oluwa won. Iyen, ohun ni oore ajulo t’o tobi

[23] Iyen ni eyi ti Allahu fi n se iro idunnu fun awon erusin Re, awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. So pe: "Emi ko beere owo-oya lowo yin lori re bi ko se ife ebi.” Enikeni ti o ba se rere kan, A maa se alekun rere fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Olope

[24] Tabi won n wi pe: "O da adapa iro mo Allahu ni?" Nitori naa, ti Allahu ba fe, O maa fi edidi di okan re pa. Ati pe Allahu yoo pa iro re. O si maa fi ododo rinle pelu oro Re. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda

[25] Oun ni Eni t’O n gba ironupiwada awon erusin Re. O n se amojukuro nibi awon asise. O si mo ohun ti e n se nise

[26] O n gba adua awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. O si n se alekun fun won ninu ola Re. Awon alaigbagbo, iya lile si wa fun won

[27] Ti o ba je pe Allahu te arisiki sile regede fun awon erusin Re ni, won iba tayo enu-ala lori ile. Sugbon O n so (arisiki) ti O ba fe kale niwon-niwon. Dajudaju Oun ni Alamotan, Oluriran nipa awon erusin Re

[28] Oun si ni Eni t’O n so omi ojo kale leyin igba ti won ti soreti nu. O si n fon ike Re ka. Oun si ni Alaabo, Eleyin

[29] Ati pe ninu ami Re ni iseda awon sanmo, ile ati nnkan ti O fonka saaarin mejeeji ninu awon nnkan abemi. Oun si ni Alagbara lori ikojo won nigba ti O ba fe

[30] Ohunkohun ti o ba kan yin ninu adanwo, ohun ti e fi owo ara yin fa ni. O si n samojukuro nibi opolopo

[31] Eyin ko si nii mori bo (mo Allahu lowo) lori ile. Ko si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu

[32] O tun wa ninu awon ami Re, awon oko oju-omi t’o n rin loju omi (t’o da) bi awon oke apata giga

[33] Ti Allahu ba fe, O maa mu ategun naa duro, (awon oko oju-omi naa) si maa di ohun ti ko nii lo mo lori omi. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe

[34] Ti Allahu ba fe, O maa mu ategun naa duro, (awon oko oju-omi naa) si maa di ohun ti ko nii lo mo lori omi. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun gbogbo onisuuru, oludupe

[35] Awon t’o n se atako si awon ayah Wa si maa mo pe ko si ibusasi kan fun won

[36] Nitori naa, ohunkohun ti A ba fun yin, igbadun aye nikan ni. Ohun ti o wa lodo Allahu loore julo, o si maa seku titi laelae fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n gbarale Oluwa won

[37] (Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o n jinna si awon ese nlanla ati awon iwa ibaje, ati (awon t’o je pe) nigba ti won ba binu, won yoo saforijin

[38] (Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon t’o jepe ti Oluwa won, ti won n kirun, oro ara won si je ijiroro laaarin ara won, won tun n na ninu arisiki ti A pese fun won

[39] (Ohun ti o wa lodo Allahu tun wa fun) awon ti (o je pe) nigba ti won ba se abosi si won, won yoo gbesan won pada

[40] Esan aburu si ni aburu bi iru re. Enikeni ti o ba si samojukuro, ti o tun satunse, esan re wa lodo Allahu. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alabosi

[41] Dajudaju eni ti o ba si gbesan leyin ti won se abosi si i, awon wonyen (ti won sabosi si), ko si ibawi kan kan fun won

[42] Awon ti ibawi wa fun ni awon t’o n sabosi si awon eniyan, ti won tun n tayo enu-ala lori ile lai letoo. Awon wonyen ni iya eleta-elero wa fun

[43] Enikeni ti o ba se suuru, ti o tun saforijin, dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan

[44] Enikeni ti Allahu ba si lona, ko tun si alaabo kan fun un mo leyin Re. O si maa ri awon alabosi nigba ti won ba ri Ina, won yoo wi pe: "Nje ona kan kan wa ti a le fi pada si ile aye

[45] O si maa ri won ti A maa ko won lo sinu Ina; won yoo palolo lati ara iyepere, won yo si maa wo fin-in-fin. Awon t’o gbagbo ni ododo si maa so pe: "Dajudaju awon eni ofo ni awon t’o se emi ara won ati ara ile won ni ofo ni Ojo Ajinde." Kiye si i, dajudaju awon alabosi yoo wa ninu iya gbere

[46] Ko si nii si alaabo kan fun won ti o maa ran won lowo leyin Allahu. Ati pe enikeni ti Allahu ba si lona, ko le si ona kan kan fun un

[47] E jepe Oluwa yin siwaju ki ojo kan to de, ti ko si idapada kan fun un ni odo Allahu. Ko si ibusasi kan fun yin ni ojo yen. Ko si nii si olukoya kan fun yin

[48] Nitori naa, ti won ba gbunri, A o ran o pe ki o je oluso fun won. Ko si kini kan t’o di dandan fun o bi ko se ise-jije. Ati pe dajudaju nigba ti A ba fun eniyan ni ike kan to wo lati odo Wa, o maa dunnu si i. Ti aburu kan ba si kan an nipase ohun ti owo won ti siwaju (ni ise aburu), dajudaju eniyan ni alaimoore

[49] Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. O n seda ohun ti O ba fe. O n ta eni ti O ba fe lore omobinrin. O si n ta eni ti O ba fe ni lore omokunrin

[50] Tabi ki O se won ni orisi meji; omokunrin ati omobinrin. O si n se eni ti O ba fe ni agan. Dajudaju Oun ni Onimo, Alagbara

[51] Ko letoo fun abara kan pe ki Allahu ba a soro afi ki (oro naa) je imisi (isipaya mimo), tabi ki o je leyin gaga, tabi ki O ran Ojise kan (ti)

[52] Bayen si ni A se fi imisi ranse si o ninu ase Wa. Iwo ko mo ki ni Tira ati igbagbo ododo tele (siwaju imisi naa),1 sugbon A se imisi naa ni imole kan ti A n fi se imona fun eni ti A ba fe ninu awon erusin Wa. Dajudaju iwo n pepe si ona taara (’Islam). 2 ise wiridi ni Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) maa n se ninu ogbun Hira siwaju ki o to di Anabi Olohun iro l’o fi pa. Idi ni pe

[53] Ona Allahu, Eni ti ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n je tiRe. Gbo! Odo Allahu ni awon oro eda yoo pada si

Ọ̀ṣọ́ wúrà

Surah 43

[1] Ha mim

[2] (Allahu) fi Tira t’o yanju oro eda bura

[3] Dajudaju Awa so o ni al-Ƙur’an. (A si so o kale ni) ede Larubawa nitori ki e le se laakaye

[4] Ati pe dajudaju ninu Tira Ipile t’o wa lodo Wa, al-Ƙur’an ga, o kun fun ogbon

[5] Se ki A ka Tira Iranti (al-Ƙur’an) kuro nile fun yin, ki A maa wo yin niran nitori pe e je ijo alakoyo

[6] Meloo meloo ninu awon Anabi ti A ti ran si awon eni akoko

[7] Ko si Anabi kan ti o wa ba won ayafi ki won maa fi se yeye

[8] Nitori naa, A ti pa awon t’o ni agbara ju awon (wonyi) re. Apejuwe (iparun) awon eni akoko si ti siwaju

[9] Ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da awon sanmo ati ile?", dajudaju won a wi pe: "Eni t’o da won ni Alagbara, Onimo

[10] Eni ti O se ile ni ite fun yin. O si fi awon oju ona sinu re fun yin nitori ki e le mona

[11] Eni ti O n so omi kale lati sanmo niwon-niwon. O si n fi so oku ile di aye ile. Bayen naa ni won yoo se mu yin jade

[12] Eni ti O seda gbogbo nnkan ni orisirisi. O si se nnkan ti e n gun fun yin lati ara awon oko oju-omi ati awon eran-osin

[13] Nitori ki e le jokoo daadaa seyin re, leyin naa ki e le se iranti idera Oluwa yin nigba ti e ba jokoo daadaa tan sori re, ki e si so pe: "Mimo ni fun Eni ti O ro eyi fun wa, ki i se pe a je alagbara lori re

[14] Ati pe dajudaju odo Oluwa wa ni awa yoo pada si

[15] Won fi ipin kan ninu awon erusin (Allahu) ti si odo Re (ni ti omo bibi). Dajudaju eniyan ni alaimoore ponnbele

[16] Tabi (eyin n wi pe): "O mu ninu nnkan ti O da ni omobinrin (funra Re). O si fi awon omokunrin sa eyin lesa

[17] Nigba ti won ba fun eni kan ninu won ni iro idunnu ohun ti o fi se apeere fun Ajoke-aye (pe onitoun bi omobinrin), oju re maa sokunkun wa. O si maa kun fun ibanuje

[18] Se eni ti won n to ninu oso (ti o n to oso mora), ti ko si le bo si gbangba nibi ija (ni e n pe ni omo Ajoke-aye)

[19] Awon molaika, awon t’o je erusin Ajoke-aye, won tun so won di omobinrin! Se won foju ri iseda won ni? Won maa se akosile ohun ti won foju ri. Won si maa bi won leere (nipa re)

[20] Won tun wi pe: "Ti Ajoke-aye ba fe, awa iba ti josin fun won." Ko si imo kan fun won nipa iyen. Won ko si je kini kan bi ko se pe won n paro

[21] Tabi A ti fun won ni Tira kan siwaju al-Ƙur’an, ti won n lo ni eri

[22] Rara. Won wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olumona lori oripa won

[23] Bakan naa, Awa ko ran olukilo kan si ilu kan siwaju re, ayafi ki awon onigbedemuke ilu naa wi pe: "Dajudaju awa ba awon baba wa lori esin kan. Dajudaju awa si ni olutele won lori oripa won

[24] (Olukilo) si so pe: "Nje emi ko ti mu wa fun yin ohun ti o je imona julo si ohun ti e ba awon baba yin lori re?" Won wi pe: "Dajudaju awa je alaigbagbo ninu ohun ti Won fi ran yin nise

[25] Nitori naa, A gbesan lara won. Wo bi ikangun awon olupe-ododo-niro ti ri

[26] (Ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so fun baba re ati awon eniyan re pe: "Dajudaju emi yowo yose kuro ninu ohun ti e n josin fun

[27] Afi Eni ti O seda mi. Dajudaju Oun l’O maa fi ona taara mo mi

[28] Allahu si se e ni oro kan t’o maa wa titi laelae laaarin awon aromodomo re nitori ki won le seri pada (sibi ododo)

[29] Sugbon Mo fun awon wonyi ati awon baba won ni igbadun aye titi ododo ati Ojise ponnbele fi de ba won

[30] Nigba ti ododo de ba won, won wi pe: "Idan ni eyi; dajudaju awa ko si nii gba a gbo

[31] Won tun wi pe: "Ki ni ko je ki Won so al-Ƙur’an yii kale fun okunrin pataki kan ninu awon ilu mejeeji

[32] Se awon ni won maa pin ike Oluwa re ni? Awa l’A pin nnkan isemi won fun won ninu igbesi aye. A si fi awon ipo giga gbe apa kan won ga ju apa kan lo nitori ki apa kan won le maa sise fun apa kan. Ike Oluwa re si loore julo si ohun ti won n ko jo

[33] Ati pe ti ki i ba se pe awon eniyan maa je ijo kan soso (lori aigbagbo ni), A iba se awon orule ati awon akaba ti won yoo fi maa gunke ninu ile ni fadaka fun eni t’o n sai gbagbo ninu Ajoke-aye

[34] (A iba tun se) awon enu ona ile won ati awon ibusun ti won yoo maa rogboku le lori (ni fadaka)

[35] ati goolu. Gbogbo nnkan wonyi ko je nnkan kan bi ko se igbadun isemi aye lasan. (Ogba Idera) Orun si wa ni odo Oluwa re fun awon oluberu (Allahu)

[36] Enikeni ti o ba gbunri kuro nibi iranti Ajoke-aye, A maa yan esu kan fun un. Oun si ni alabaarin re

[37] Dajudaju awon esu naa yoo maa seri won kuro loju ona (esin Allahu). Won yo si maa lero pe dajudaju awon ni olumona

[38] Titi di igba ti o fi maa wa ba Wa, o si maa wi pe: "Haa! Ki o si je pe (itakete bi) itakete ibuyo-oorun ati ibuwo re si wa laaarin emi ati iwo (esu alabaarin yii, iba dara); alabaarin buruku si ni

[39] (Abamo yin) ko nii se yin ni anfaani ni Oni nigba ti e ti sabosi. (Ati pe) dajudaju eyin (ati orisa yin) ni akegbe ninu iya

[40] Se iwo l’o maa fun awon aditi ni oro gbo tabi o maa fun awon afoju ni imona ati eni ti o wa ninu isina ponnbele

[41] Nitori naa, o see se ki A ti mu o kuro (lori ile aye siwaju asiko iya won), dajudaju Awa yoo gbesan (iya) lara won

[42] Tabi ki A fi ohun ti A se ni ileri fun won han o, dajudaju Awa je Alagbara lori won

[43] Nitori naa, di ohun ti A fi ranse si o mu sinsin. Dajudaju iwo wa loju ona taara (’Islam)

[44] Dajudaju al-Ƙur’an ni tira iranti fun iwo ati ijo re. Laipe Won maa bi yin leere (nipa re)

[45] Beere wo lowo awon ti A ran nise siwaju re ninu awon Ojise Wa (pe): "Nje A so awon kan di olohun ti won yoo maa josin fun leyin Ajoke-aye bi

[46] A kuku fi awon ami Wa ran (Anabi) Musa nise si Fir‘aon ati awon ijoye re. O si so pe: "Dajudaju emi ni Ojise Oluwa gbogbo eda

[47] Sugbon nigba ti o mu awon ami Wa wa ba won, nse ni won n fi awon ami naa rerin-in nigba naa

[48] A o si nii fi ami kan han won ayafi ki o tobi ju iru re (t’o siwaju). A si fi iya je won nitori ki won le seri pada (sibi ododo)

[49] Won si wi pe: "Iwo opidan, pe Oluwa re fun wa nitori adehun ti O se pelu re. Dajudaju awa maa tele imona Re

[50] Sugbon nigba ti A mu iya kuro fun won, nigba naa ni won tun n ye adehun

[51] Fir‘aon si pepe laaarin awon eniyan re, o wi pe: "Eyin eniyan mi, se temi ko ni ijoba Misro ati awon odo wonyi t’o n san nisale (odo) mi? Se e o riran ni

[52] Tabi se emi ko loore julo si eyi ti o je ole yepere, ti o fee ma le da oro so yanju

[53] Ki ni ko je ki Won fun un ni awon egba-owo goolu tabi (ki ni ko je ki) awon molaika wa pelu re, ki won je alabaarin (ti won yoo maa jerii re)

[54] Nitori naa, o so awon eniyan re dope. Won si tele e. Dajudaju won je ijo obileje

[55] Nigba ti won wa ibinu Wa, A gba esan (iya) lara won. Nitori naa, A te gbogbo won ri (sinu agbami odo)

[56] A si se won ni ijo asiwaju (ninu iparun) ati apeere (feyikogbon) fun awon eni ikeyin

[57] Nigba ti awon osebo fi omo Moryam se apeere (fun orisa won), nigba naa ni awon eniyan re ba n fi (apeere naa) rerin-in

[58] Won si wi pe: "Se awon orisa wa l’o loore julo ni tabi oun? Won ko wule fi sapeere fun o bi ko se (fun) atako. Ani se, ijo oniyanjija ni won

[59] Ki ni oun bi ko se erusin kan ti A se idera fun. A si se e ni apeere rere fun awon omo ’Isro’il

[60] Ti o ba je pe A ba fe, A iba maa fi awon molaika ropo yin lori ile

[61] Dajudaju oun ni imo (tabi ami fun isunmo) Akoko naa. Nitori naa, e o gbodo seyemeji nipa re. Ki e si tele mi. Eyi ni ona taara

[62] E ma se je ki Esu se yin lori; dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

[63] Nigba ti (Anabi) ‘Isa de pelu awon eri t’o yanju, o so pe: "Dajudaju mo de wa ba yin pelu ijinle ogbon. (Mo si de) nitori ki ng le se alaye apa kan eyi ti e n yapa enu nipa re fun yin. Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi

[64] Dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara

[65] Awon ijo (re) si yapa (esin ’Islam) laaarin ara won. Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sabosi ni ojo iya eleta-elero

[66] Se won n reti kini kan bi ko se Akoko naa; ti o maa de ba won ni ojiji; won ko si nii fura

[67] Awon ore ayo ni ojo yen, apa kan won yoo je ota fun apa kan ayafi awon oluberu (Allahu)

[68] Eyin erusin Mi, ko si iberu fun yin ni oni. Eyin ko si nii banuje

[69] (Awon ni) awon t’o gbagbo ninu awon ayah Wa, ti won si je musulumi (olujuwo-juse sile fun Allahu)

[70] E wo inu Ogba Idera, eyin ati awon iyawo yin; ki e maa dunnu

[71] Won yoo maa gbe awon awo goolu ati awon ife imumi kaa kiri odo won. Ohun ti emi n fe ati (ohun ti) oju yoo maa dunnu si wa ninu re. Olusegbere si ni yin ninu re

[72] Iyen ni Ogba Idera ti A jogun re fun yin nitori ohun ti e n se nise

[73] Eso pupo wa fun yin ninu re. Eyin yo si maa je ninu re

[74] Dajudaju awon elese ni olusegbere ninu iya ina Jahanamo

[75] A o nii gbe e fuye fun won. Won yo si soreti nu ninu Ina

[76] A o sabosi si won, sugbon awon ni won je alabosi

[77] Won yoo pe (molaika kan) pe: "Molik (eso Ina), je ki Oluwa re pa wa raurau." (Molik) yoo so pe: "Dajudaju eyin yoo maa gbe inu re ni

[78] Dajudaju A ti mu ododo wa ba yin, sugbon opolopo yin korira ododo

[79] Tabi awon (alaigbagbo) ti pinnu oro kan ni? Dajudaju Awa naa n pinnu oro

[80] Tabi won n lero pe Awa ko gbo oro asiri won ati oro ikoko won? Rara (A n gbo); awon Ojise Wa wa ni odo won, ti won n se akosile (oro won)

[81] So pe: "Ko si omo kan fun Ajoke aye. Nitori naa, emi ni eni akoko ninu awon olujosin (fun Allahu ni asiko temi)

[82] Mimo ni fun Oluwa awon sanmo ati ile, Oluwa Ite-ola tayo iro ti won n pa (mo On)

[83] Nitori naa, fi won sile ki won maa so isokuso (won), ki won si maa sere won lo titi won yoo fi pade ojo won, ti A n se ni adehun fun won

[84] (Allahu) Oun ni Olohun Eni ti ijosin to si ninu sanmo. Oun naa si ni Olohun Eni ti ijosin to si lori ile. Oun ni Ologbon, Onimo

[85] Ibukun ni fun Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji. Odo Re si ni imo Akoko naa wa. Odo Re si ni won maa da yin pada si

[86] Awon ti won n pe leyin Re, won ko kapa isipe ayafi eni ti o ba jerii si ododo (kalmotus-sahaadah), ti won si nimo (re)

[87] Ati pe ti o ba bi won leere pe: "Ta ni O da won?", dajudaju won a wi pe: "Allahu ni." Nitori naa, bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo

[88] Oro (ti Anabi n so fun Allahu ni pe): "Oluwa Mi, dajudaju awon wonyi ni ijo ti ko gbagbo.”

[89] Nitori naa, samoju kuro fun won, ki o si so pe: "Alaafia!" Laipe won maa mo

Èéfín

Surah 44

[1] Ha mim

[2] (Allahu) bura pelu Tira t’o yanju oro eda

[3] Dajudaju Awa so o kale ninu oru ibukun. Dajudaju Awa n je Olukilo

[4] Ninu oru naa ni won ti maa yanju gbogbo oro ti ko nii tase (lori eda)

[5] Ase kan ni lati odo Wa. Dajudaju Awa l’A n ran awon Ojise nise

[6] Ike kan ni lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Onimo

[7] Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin mejeeji ti eyin ba je alamodaju

[8] Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko

[9] Sibe, won si wa ninu iyemeji, ti won n sere

[10] Nitori naa, maa reti ojo ti sanmo yoo mu eefin ponnbele wa

[11] O maa bo awon eniyan mole. Eyi ni iya eleta-elero

[12] (Awon eniyan yoo wi pe): Oluwa wa, gbe iya naa kuro fun wa, dajudaju awa yoo gbagbo ni ododo

[13] Bawo ni iranti se le wulo fun won (lasiko iya)? Ojise ponnbele kuku ti de ba won

[14] Leyin naa, won gbunri kuro ni odo re. Won si wi pe: "Were ti eniyan kan n ko ni eko ni

[15] Dajudaju Awa maa gbe iya naa kuro fun igba die. Dajudaju eyin yoo tun pada (sinu aigbagbo)

[16] Ojo ti A oo gba (won mu) ni igbamu t’o tobi julo; dajudaju Awa yoo gba esan iya (lara won)

[17] Dajudaju A dan awon eniyan Fir‘aon wo siwaju won. Ojise alapon-onle si de wa ba won

[18] (O so pe): “E ko awon erusin Allahu le mi lowo. Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin

[19] E ma se segberaga si Allahu. Dajudaju emi ti mu eri ponnbele wa ba yin

[20] Dajudaju Emi sa di Oluwa mi ati Oluwa yin pe ki e ma se so mi loko pa

[21] Ti e ko ba si gba mi gbo, e fi mi sile je

[22] Nitori naa, o pe Oluwa re pe dajudaju awon wonyi ni ijo elese

[23] (Allahu so pe): "Mu awon erusin Mi rin ni ale (nitori pe) won yoo to yin leyin

[24] Ki o si fi agbami odo sile ni yiyanu sile bee. Dajudaju awon ni omo ogun ti A maa teri sinu agbami

[25] Meloo meloo ninu awon ogba oko ati odo iseleru ti won fi sile (leyin iparun won)

[26] Ati awon irugbin pelu aye aponle (ti won fi sile)

[27] Ati idera ti won n gbadun ninu re (siwaju iparun won)

[28] Bayen (ni oro won se ri). A si jogun (ilu) won fun ijo eniyan miiran

[29] Nigba naa, sanmo ati ile ko sunkun won. Won ko si fi iya won fale

[30] Dajudaju A gba awon omo ’Isro’il la ninu iya yepere

[31] (A la won) lowo Fir‘aon. Dajudaju o je onigbeeraga. O si wa ninu awon alakoyo

[32] A kuku sa won lesa lori awon eda (asiko tiwon) pelu imo

[33] A si fun won ni awon ami ti adanwo ponnbele wa ninu re

[34] Dajudaju awon wonyi n wi pe

[35] Ko si iku kan ayafi iku akoko (ti o pa wa nile aye). Won ko si nii gbe wa dide

[36] (Bi bee ko), e mu awon baba wa wa ti e ba je olododo

[37] Se awon ni won loore julo ni tabi awon eniyan Tubba‘u ati awon t’o siwaju won? A pa won re; dajudaju won je elese

[38] A ko seda awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin mejeeji pelu ere sise

[39] A ko da awon mejeeji bi ko se pelu ododo, sugbon opolopo won ni ko mo

[40] Dajudaju ojo opinya (iyen, ojo ajinde) ni akoko adehun fun gbogbo won patapata

[41] Ni ojo ti ore kan ko nii fi kini kan ro ore kan loro. A o si nii ran won lowo

[42] Ayafi eni ti Allahu ba ke. Dajudaju Allahu, Oun ni Alagbara, Asake-orun

[43] Dajudaju igi zaƙum

[44] ni ounje elese

[45] O da bi epo gbigba ti n ho ninu ikun

[46] (t’o) da bi hiho omi gbigbona

[47] E mu un. Ki e wo o saarin gbungbun inu ina Jehim

[48] Leyin naa, e ro iya olomi gbigbona le e lori

[49] To o wo (sebi) dajudaju iwo ni alagbara, alapon-onle (gege bi o se pe ara re)

[50] Dajudaju (iya) eyi ni nnkan ti e n seyemeji nipa re

[51] Dajudaju awon oluberu Allahu yoo wa ni aye ifayabale

[52] (Won yoo wa) ninu awon Ogba Idera pelu awon omi iseleru (ni isale re)

[53] Won yoo maa wo aso aran felefele ati aran t’o nipon; won yo si maa koju sira won

[54] Bayen (ni oro won yo se ri). A si maa fi awon obinrin eleyinju-ege se iyawo fun won

[55] Won yoo maa beere fun gbogbo nnkan eleso ninu (Ogba Idera) pelu ifayabale

[56] Won ko nii to iku wo nibe ayafi iku akoko (ti won ti ku nile aye). (Allahu) si maa so won nibi iya ina Jehim

[57] O je oore ajulo lati odo Oluwa re. Iyen ni erenje nla

[58] Nitori naa, A se (al-Ƙur’an) ni irorun lori ahon re nitori ki won le lo iranti

[59] Nitori naa, maa reti . Dajudaju awon naa n reti

Títẹríba

Surah 45

[1] Ha mim

[2] Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon

[3] Dajudaju ninu awon sanmo ati ile awon ami wa (ninu won) fun awon onigbagbo ododo

[4] Awon ami wa ninu iseda yin ati ohun ti Allahu n fonka (sori ile) ninu awon nnkan abemi; (ami wa ninu won) fun ijo t’o ni amodaju

[5] (Ninu) itelentele ati iyato oru ati osan, ati ohun ti Allahu n sokale ni arisiki, ti O n fi so ile di aye leyin t’o ti ku ati iyipada ategun, awon ami tun wa (ninu won) fun ijo t’o ni laakaye

[6] Iwonyi ni awon ayah Allahu ti A n ke (ni keu) fun o pelu ododo. Nitori naa, oro wo leyin (oro) Allahu ati awon ami Re ni won yoo tun gbagbo

[7] Egbe ni fun aladaapaaro, elese

[8] t’o n gbo awon ayah Allahu, ti won n ke e fun un, leyin naa, ti o (tun) taku ni ti igberaga bi eni pe ko gbo o. Fun un ni iro iya eleta-elero

[9] Nigba ti o ba nimo nipa kini kan ninu awon ayah Wa, o maa mu un ni nnkan yeye. Awon wonyen ni iya ti i yepere eda n be fun

[10] Ina Jahanamo wa niwaju won. Ohun ti won se nise ati ohun ti won mu ni alaabo leyin Allahu ko si nii ro won loro kan nibi iya. Iya nla si wa fun won

[11] Eyi ni imona. Awon t’o si sai gbagbo ninu awon ayah Oluwa won, iya elegbin eleta-elero wa fun won

[12] Allahu ni Eni ti O ro agbami odo fun yin nitori ki awon oko oju-omi le rin ninu re pelu ase Re ati nitori ki e tun le wa ninu oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Un)

[13] O tun ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile patapata fun yin lati odo ara Re. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle

[14] So fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki won samoju kuro fun awon ti ko reti awon ojo (ti) Allahu (yoo se aranse fun awon onigbagbo ododo) nitori ki O le san esan fun ijo kan nipa ohun ti won n se nise

[15] Enikeni ti o ba se ise rere, fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si se ise aburu, fun emi ara re ni. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won yoo da yin pada si

[16] Dajudaju A fun awon omo ’Isro’il ni Tira ati idajo sise pelu ipo Anabi. A si se arisiki fun won ninu awon nnkan daadaa. A si soore ajulo fun won lori awon eda (asiko won)

[17] A tun fun won ni awon eri t’o yanju nipa oro naa. Nitori naa, won ko pin si ijo otooto afi leyin ti imo (’Islam) de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Dajudaju Oluwa re l’O maa se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa nnkan ti won n yapa enu si

[18] Leyin naa, A fi o si oju ona kan ninu oro (esin ’Islam). Nitori naa, tele e. Ki o si ma se tele ife-inu awon ti ko nimo

[19] Dajudaju won ko le ro o loro kini kan nibi iya ni odo Allahu. Ati pe dajudaju awon alabosi, apa kan won lore apa kan. Allahu si ni Ore awon oluberu (Re)

[20] Eyi ni itosona fun awon eniyan. Imona ati ike ni fun ijo t’o ni amodaju

[21] Tabi awon t’o n se ise aburu lero pe A maa se won gege bi (A ti se) awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, ki isemi aye won ati iku won ri bakan naa? Ohun ti won n da lejo buru

[22] Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo ati nitori ki A le san emi kookan ni esan nnkan ti o se nise. A o si nii se abosi si won

[23] So fun mi nipa eni ti o so ife-inu re di olohun re, ti Allahu si si i lona pelu imo , ti O si fi edidi di igboro re ati okan re, ti O tun fi ebibo bo oju re! Ta ni o maa fi ona mo on leyin Allahu? Se e o nii lo iranti ni

[24] Won wi pe: "Ko si isemi kan mo bi ko se isemi aye wa yii; a n ku, a si n semi. Ati pe ko si nnkan t’o n pa wa bi ko se igba." Won ko si ni imo kan nipa iyen; won ko se kini kan bi ko se pe won n ro erokero

[25] Ati pe nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awijare won ko je kini kan tayo ki won wi pe: "E mu awon baba wa wa ti e ba je olododo

[26] So pe: "Allahu l’O n so yin di alaaye. Leyin naa, O maa so yin di oku. Leyin naa, O maa ko yin jo ni Ojo Ajinde, ko si iyemeji ninu re, sugbon opolopo eniyan ni ko mo

[27] Ati pe ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. (Ranti) ojo ti Akoko naa maa sele; ojo yen ni awon t’o n tele iro yoo sofo

[28] O si maa ri gbogbo ijo lori ikunle. Won yo si maa pe ijo kookan sibi iwe ise won. Ni oni ni A oo san yin ni esan ohun ti e n se nise

[29] Eyi ni iwe akosile Wa, ti o n so ododo nipa yin. Dajudaju Awa n se akosile ohun ti e n se nise

[30] Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, Oluwa won yoo fi won sinu ike Re. Iyen ni erenje ponnbele

[31] Ni ti awon t’o si sai gbagbo, (A oo bi won leere pe:) "Nje won ki i ke awon ayah Mi fun yin bi?" Sugbon e segberaga. E si je ijo elese

[32] Nigba ti won ba so pe: "Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ati pe Akoko naa, ko si iyemeji ninu re." Eyin n wi pe: "Awa ko mo ohun ti Akoko naa je. Awa ko si ro o si kini kan bi ko se erokero; awa ko si ni amodaju (nipa re)

[33] Awon aburu ohun ti won se nise si han si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po

[34] Won si maa so pe: "Ni oni, Awa yoo gbagbe yin (sinu Ina) gege bi eyin naa se gbagbe ipade ojo yin (oni) yii. Ina si ni ibugbe yin. Ati pe ko nii si awon oluranlowo fun yin

[35] Bayen ni nitori pe, e so awon ayah Allahu di nnkan yeye. Ati pe isemi aye tan yin je. Nitori naa, ni oni won ko nii mu won jade kuro ninu Ina. Won ko si nii fun won ni aye lati se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu

[36] Nitori naa, gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa awon sanmo ati ile, Oluwa gbogbo eda

[37] TiRe ni titobi ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon

Àwọn Ìyàngbẹ Ilẹ̀

Surah 46

[1] Ha mim

[2] Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon

[3] A o seda awon sanmo ati ile, ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji bi ko se pelu ododo ati fun gbedeke akoko kan. Awon t’o sai gbagbo yo si maa gbunri kuro nibi ohun ti A fi sekilo fun won

[4] So pe: "E so fun mi nipa nnkan ti e n pe leyin Allahu; e fi won han mi na, ki ni won seda ninu (ohun t’o wa lori) ile. Tabi won ni ipin kan (pelu Allahu) ninu (iseda) awon sanmo? E mu Tira kan wa fun mi t’o siwaju (al-Ƙur’an) yii tabi oripa kan ninu imo ti e ba je olododo

[5] Ta l’o si sina ju eni ti o n pe leyin Allahu, eni ti ko le je ipe re titi di Ojo Ajinde! Ati pe won ko ni oye si pipe ti won n pe won

[6] Nigba ti A ba si ko awon eniyan jo (fun Ajinde), awon orisa yoo di ota fun awon aborisa. Won si maa tako ijosin ti won se fun won

[7] Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awon t’o sai gbagbo yo si maa so isokuso si ododo nigba ti o de ba won pe: "Eyi ni idan ponnbele

[8] Tabi won n wi pe: "O da (al-Ƙur’an) hun funra re ni." So pe: "Ti mo ba hun un funra mi, e o ni ikapa kini kan fun mi ni odo Allahu (nibi iya Re). Oun ni Onimo-julo nipa isokuso ti e n so nipa re. O (si) to ni Elerii laaarin emi ati eyin. Oun ni Alaforijin, Asake-orun

[9] So pe: "Emi ki i se akoko ninu awon Ojise. Emi ko si mo nnkan ti won maa se fun emi ati eyin. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi. Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele." won wa labe ijoba awon osebo ninu ilu Mokkah alapon-onle. Won si bere si nii yowo kowo si awon omoleyin Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam). Lasiko naa ipo ole ni awon musulumi wa ninu ilu naa. Ko si ohun t’o wa le fi won lokan bale sinu ’Islam tayo ki Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) je ki o di mimo fun eni kookan awon omoleyin re pe ijiya ati pipa han awon musulumi ni eemo ifoju-egbo-rin. Mo daju pe ko si Anabi kan ninu awon Anabi Olohun (ahm.s.w.) ti ko mo pe ti o ba je pe itumo ti awon kristieni fun ayah naa l’o ba je ododo “emi ko si mo nnkan ti Allahu maa se fun emi ati eyin” ni iba je agbekale re. Bakan naa ise ti Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) je faye ko yato si ti awon t’o siwaju re ninu awon Ojise Allahu (ahm.s.w). Bakan naa ayah naa n pe wa sibi iduro sinsin ati atemora lasiko inira awon alaigbagbo

[10] So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe lati odo Allahu ni (al-Ƙur’an) ti wa, ti e si sai gbagbo ninu re, ti elerii kan ninu awon omo ’Isro’il si jerii lori iru re, ti o si gba a gbo, (amo) ti eyin segberaga si i, (se e o ti sabosi bayen bi?). Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

[11] Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo pe: "Ti o ba je pe al-Ƙur’an je oore ni, won ko nii siwaju wa debe." Nigba ti awon osebo ko ti tele imona re, ni won n wi pe: "Iro ijoun ni eyi

[12] Tira (Anabi) Musa si ti wa siwaju re, ti o je tira ti won n tele, o si je ike (fun won. Al-Ƙur’an) yii tun ni Tira kan t’o n jerii si ododo ni ede Larubawa nitori ki o le sekilo fun awon t’o sabosi, (o si je) iro idunnu fun awon oluse-rere

[13] Dajudaju awon t’o so pe: "Allahu ni Oluwa wa", leyin naa, ti won duro sinsin, ko nii si ipaya fun won. Won ko si nii banuje

[14] Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise

[15] A pa a ni ase fun eniyan pe ki o maa se daadaa si awon obi re mejeeji. Iya re ni oyun re pelu wahala. O si bi i pelu wahala. Oyun re ati gbigba omu lenu re je ogbon osu. (O si n to o) titi o fi dagba, ti o fi di omo ogoji odun, o si so pe: "Oluwa mi, fi mo mi ki ng maa dupe idera Re, eyi ti O fi se idera fun mi ati fun awon obi mi mejeeji, ki ng si maa se ise rere, eyi ti O yonu si. Ki O si se rere fun mi lori awon aromodomo mi. Dajudaju emi ti ronu piwada si odo Re. Dajudaju emi si wa ninu awon musulumi

[16] Awon wonyen ni awon ti A maa gba ise rere ti won se nise, A si maa se amojukuro nibi awon aburu ise won; won maa wa ninu awon ero inu Ogba Idera. (O je) adehun ododo ti A n se ni adehun fun won

[17] Eni ti o so fun awon obi re mejeeji pe: "Sio eyin mejeeji! Se eyin yoo maa seleri fun mi pe Won yoo mu mi jade (laaye lati inu saree), sebi awon iran kan ti re koja lo siwaju mi (ti Won ko ti i mu won jade lati inu saree won)." Awon (obi re) mejeeji si n toro igbala ni odo Allahu (fun omo yii. Won si so pe): "Egbe ni fun o! (O je) gbagbo ni ododo. Dajudaju adehun Allahu ni ododo." (Omo naa si) wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko

[18] Awon (alaigbagbo) wonyen ni awon ti oro naa ti ko le lori ninu awon ijo kan ti o ti re koja siwaju won ninu awon alujannu ati eniyan. Dajudaju won je eni ofo

[19] Awon ipo yoo wa fun eni kookan nipa ise ti won se nise. Ati pe (eyi ri bee) nitori ki (Allahu) le san won ni esan ise won. Awa ko si nii sabosi si won

[20] Ni ojo ti won maa dari awon t’o sai gbagbo ko Ina, (won maa so fun won pe:) "E ti lo igbadun yin tan ninu isemi aye? E si ti je igbadun aye? Nitori naa, ni oni, won maa san yin ni esan abuku iya nitori pe e n segberaga ni ori ile lai letoo ati nitori pe e n sebaje

[21] Seranti arakunrin (ijo) ‘Ad. Nigba ti o sekilo fun awon eniyan re t’o n gbe ninu yanrin ti ategun kojo bi oke. Awon olukilo si ti re koja siwaju re ati leyin re. (O si so pe:) "Eyin ko gbodo josin fun kini kan ayafi Allahu. Dajudaju emi n paya iya ojo nla kan fun yin

[22] Won wi pe: "Se iwo wa ba wa lati se wa lori kuro nibi awon orisa wa ni? Mu ohun ti o n se ileri re fun wa wa ti iwo ba wa ninu awon olododo

[23] O so pe: "Imo (nipa re) wa ni odo Allahu nikan soso. Emi yo si je ise ti Won fi ran mi de opin fun yin, sugbon emi n ri eyin ni ijo alaimokan

[24] Nigba ti won ri iya naa ni esujo regede, t’o n wo bo wa sinu awon koto ilu won, won wi pe: "Eyi ni esujo regede, ti o maa rojo fun wa." Ko si ri bee, ohun ti e n wa pelu ikanju ni. Ategun ti iya eleta-elero wa ninu re ni

[25] O n pa gbogbo nnkan re pelu ase Oluwa re. Nigba naa, won di eni ti won ko ri mo afi awon ibugbe won. Bayen ni A se n san ijo elese ni esan

[26] A kuku fun won ni ipo ti A o fun eyin. A si fun won ni igboro, awon iriran ati awon okan. Amo igboro won ati awon iriran won pelu awon okan won ko ro won loro kan kan nibi iya nitori pe won n se atako si awon ayah Allahu. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po

[27] Awa kuku ti pa re ninu awon ilu ti o wa ni ayika yin. Awa si ti salaye awon ayah naa ni orisirisi ona nitori ki won le seri pada (sibi ododo)

[28] Awon olohun ti won so di ohun ti o maa mu won sunmo (igbala) leyin Allahu ko se ran won lowo mo? Rara (ko le si aranse fun won)! Won ti dofo mo won lowo. Iyen si ni (olohun) iro won ati ohun ti won n da ni adapa iro

[29] (Ranti) nigba ti A dari ijo kan ninu awon alujannu si o, ti won n teti gbo al-Ƙur’an. Nigba ti won de sibe, won so pe: "E dake (fun al-Ƙur’an)." Nigba ti won si pari (kike re tan), won pada si odo ijo won, ti won n sekilo (fun won)

[30] Won so pe: "Eyin ijo wa, dajudaju awa gbo (nipa) Tira kan ti won sokale leyin (Anabi) Musa, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re, ti o si n toni si ona ododo ati ona taara

[31] Eyin ijo wa, e je ipe olupepe Allahu. Ki e si gba a gbo ni ododo. (Allahu) yo si fori awon ese yin jin yin. O si maa yo yin kuro ninu iya eleta-elero

[32] Enikeni ti ko ba si jepe olupepe Allahu, ko le mori bo mo (Allahu) lowo lori ile. Ko si si alaabo kan fun un leyin Allahu. Awon wonyen si wa ninu isina ponnbele

[33] Se won ko ri i pe dajudaju Allahu, Eni ti O da awon sanmo ati ile, ti ko si kaaare nipa iseda won, (se ko) ni agbara lati so awon oku di alaaye ni? Rara, (O lagbara lati se bee). Dajudaju O n je Alagbara lori gbogbo nnkan

[34] (Ranti) ojo ti won maa dari awon t’o sai gbagbo lo sori Ina, (won si maa so fun won pe:) "Se eyi ki i se ododo bi?" Won yoo wi pe: "Rara, (ododo ni) Oluwa wa." (Allahu maa) so pe: "Nitori naa, e to iya wo nitori pe eyin je alaigbagbo

[35] Nitori naa, se suuru gege bi awon onipinnu okan ninu awon Ojise ti se suuru. Ma se ba won wa iya pelu ikanju. Ni ojo ti won ba ri ohun ti A n se ni adehun fun won, won yoo da bi eni pe won ko gbe ile aye (yii) tayo akoko kan ninu osan. Al-Ƙur’an yii si ni ijise dopin. Ta ni o si maa parun bi ko se ijo obileje

Muhammad

Surah 47

[1] Awon t’o sai gbagbo, ti won tun seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, (Allahu) maa so ise won dofo

[2] Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won tun gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun (Anabi) Muhammad, ohun si ni ododo lati odo Oluwa won, (Allahu) maa pa awon (ise) aburu won re, O si maa se atunse oro won si daadaa

[3] Iyen nitori pe dajudaju awon t’o sai gbagbo tele iro. Ati pe dajudaju awon t’o gbagbo tele ododo lati odo Oluwa won. Bayen ni Allahu se n fi apejuwe won lele fun awon eniyan

[4] Nitori naa, nigba ti e ba pade awon t’o sai gbagbo (loju ogun esin), e maa be won lorun nso titi di igba ti e maa fi bori won. (Ti e ba segun) ki e de won nigbekun. Leyin naa, e le tu won sile ni ofe tabi ki e tu won sile pelu owo itusile titi (okunfa) ogun esin yoo fi kase nile. Iyen (wa bee). Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba gbesan funra Re (lai nii la ogun jija lo), sugbon nitori ki O le dan apa kan yin wo lara apa kan ni. Awon musulumi ti won si pa si oju ogun esin, Allahu ko nii so ise won dofo

[5] O maa to won sona. O si maa tun oro won se si daadaa

[6] O maa fi won wo inu Ogba Idera, eyi ti O ti fi mo won

[7] Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba ran (esin) Allahu lowo, (Allahu) maa ran yin lowo. O si maa mu ese yin duro sinsin

[8] Awon t’o sai gbagbo, egbe ni fun won. (Allahu) si maa ba ise won je

[9] Iyen nitori pe dajudaju won korira ohun ti Allahu sokale. Nitori naa, (Allahu) si ba ise won je

[10] Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Allahu pa won re. Iru re tun wa fun awon alaigbagbo

[11] Iyen nitori pe dajudaju Allahu ni Oluranlowo awon t’o gbagbo ni ododo. Dajudaju awon alaigbagbo, ko si oluranlowo kan fun won

[12] Dajudaju Allahu yoo fi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Awon t’o si sai gbagbo, awon n gbadun, won si n je (kiri) gege bi awon eran-osin se n je (kiri). Ina si ni ibugbe fun won

[13] Meloo meloo ninu awon (ara) ilu ti o lagbara ju (ara) ilu re, ti o le o jade, ti A si ti pa won re. Ko si si alaranse kan fun won

[14] Nje eni ti o wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa re, se o da bi eni ti won se ise aburu re ni oso fun, ti won si tele ife-inu won

[15] Apejuwe Ogba Idera eyi ti Won se ni adehun fun awon oluberu Allahu (niyi): awon omi odo wa ninu re ti ko nii yi pada ati awon odo wara ti adun re ko nii yi pada ati awon odo oti didun fun awon t’o maa mu un ati awon odo oyin mimo. Awon oniruuru eso wa fun won ninu re ati aforijin lati odo Oluwa won. (Se eni ti o wa ninu Ogba Idera yii) da bi olusegbere ninu Ina bi, ti won n fun won ni omi gbigbona mu, ti o si maa ja awon ifun won putuputu

[16] O wa ninu won, eni ti o teti si oro re titi di igba ti won ba jade kuro ni odo re tan, won yo si wi fun awon onimo-esin pe: "Ki l’o so leee kan na?" Awon wonyen ni awon ti Allahu ti di okan won pa. Won si tele ife-inu won

[17] Awon t’o si tele imona, (Allahu) salekun imona fun won. O si maa fun won ni iberu won (ninu Allahu)

[18] Se won n reti kini kan bi ko se Akoko naa, ti o maa de ba won ni ojiji? Awon ami re kuku ti de. Nitori naa, bawo ni iranti (yo se wulo fun) won nigba ti o ba de ba won

[19] Nitori naa, mo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu. Ki o si toro aforijin fun ese re ati fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin. Allahu mo lilo-bibo yin ati ibusinmi yin

[20] Awon t’o gbagbo ni ododo n so pe: "Ki ni ko je ki Won so surah kan kale?" Nigba ti won ba so surah alainipon-na kale, ti won si so oro ija ogun esin ninu re, iwo yoo ri awon ti arun wa ninu okan won, ti won yoo maa wo o ni wiwo bi eni pe won ti daku lo ponrangandan. Ohun ti o si dara julo fun won

[21] ni itele ase (Allahu) ati (siso) oro rere. Nigba ti ogun esin si ti di dandan, won iba ni igbagbo ododo ninu Allahu, iba dara julo fun won

[22] Nje ko sunmo ti eyin (alaisan okan wonyi) ba de’po ase, pe e o nii sebaje lori ile ati pe e o nii ja okun-ibi yin

[23] Awon wonyen ni awon ti Allahu ti sebi le. Nitori naa, O di won leti pa. O si fo iriran won

[24] Se won ko nii ronu nipa al-Ƙur’an ni tabi awon agadagodo ti wa lori okan won ni

[25] Dajudaju awon t’o peyin da (si ’Islam) leyin ti imona ti foju han si won, Esu lo se isina ni oso fun won. O si fun won ni ireti asan nipa emi gigun

[26] Iyen nitori pe (awon alaisan okan) n so fun awon t’o korira ohun ti Allahu sokale pe: "Awa yoo tele yin ninu apa kan oro naa." Allahu si mo asiri won

[27] Bawo ni (o se maa ri) nigba ti awon molaika ba gba emi won, ti won yo si maa gba oju won ati eyin won

[28] Iyen nitori pe dajudaju won tele ohun ti o bi Allahu ninu. Won si tun korira iyonu Re. Nitori naa, Allahu ti ba awon ise won je

[29] Tabi awon ti arun wa ninu okan won n lero pe Allahu ko nii se afihan adisokan buruku won ni

[30] Ati pe ti A ba fe Awa iba fi won han o, iwo iba si mo won pelu ami won. Dajudaju iwo yoo mo won nipa ipekoro-soro (won). Allahu si mo awon ise (owo) yin

[31] Dajudaju A maa dan yin wo titi A fi maa safi han awon olujagun-esin ati awon onisuuru ninu yin. A si maa gbidanwo awon iro yin

[32] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, ti won tun ko inira ba Ojise Allahu leyin ti imona ti foju han si won, won ko le ko inira kini kan ba Allahu. (Allahu) yo si ba ise won je

[33] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele (oro) Allahu, e tele (oro) Ojise naa, ki e si ma se ba awon ise yin je

[34] Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, leyin naa ti won ku nigba ti won je alaigbagbo, Allahu ko nii forijin won

[35] E ma se kaaare, ki e si ma se pepe fun kosogunmo, nigba ti e ba n leke lowo. Allahu wa pelu yin; ko si nii ko adinku ba esan awon ise yin

[36] Ere ati iranu ni isemi aye. (Amo) ti e ba gbagbo (ninu Allahu), ti e si beru (Re), O maa fun yin ni awon esan yin. Ko si nii beere awon dukia yin (pe ki e fi gbogbo re yo Zakah)

[37] Ti (Allahu) ba beere re ni owo yin (pe ki e fi gbogbo re yo Zakah), ti O si wonkoko mo yin, e maa sahun. O si maa mu arun okan yin jade (asiri yin yo si tu sita)

[38] Eyin naa ma niwonyi ti won n pe lati nawo fun esin Allahu. Sugbon eni t’o n sahun wa ninu yin. Enikeni ti o ba sahun, o se e fun emi ara re. Allahu ni Oloro. Eyin si ni alaini. Ti e ba gbunri, (Allahu) maa fi ijo miiran paaro yin. Leyin naa, won ko si nii da bi iru yin

Ìṣẹ́gun

Surah 48

[1] Dajudaju Awa fun o ni isegun ponnbele

[2] nitori ki Allahu le saforijin ohun ti o siwaju ninu asise re ati ohun ti o keyin (ninu re), ati nitori ki O le sasepe idera Re le o lori ati nitori ki O le fi ese re rinle soju ona taara (’Islam)

[3] ati nitori ki Allahu le saranse fun o ni aranse t’o lagbara

[4] Oun ni Eni ti O so ifayabale sinu okan awon onigbagbo ododo nitori ki won le lekun ni igbagbo si igbagbo won. Ti Allahu si ni awon omo ogun sanmo ati ile. Allahu si n je Onimo, Ologbon

[5] (O se bee fun won) nitori ki O le mu awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re, olusegbere ni won ninu re, ati nitori ki O le pa awon asise won re. Iyen si je erenje nla ni odo Allahu

[6] Ati nitori ki O le fiya je awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumi lobinrin, pelu awon osebo lokunrin ati awon osebo lobinrin, awon elerokero nipa Allahu ni ti ero aburu. Apadasi aburu n be fun won. Allahu ti binu si won. O ti sebi le won. O si ti pese ina Jahnamo sile de won. O si buru ni ikangun

[7] Ti Allahu si ni awon omo ogun sanmo ati ile. Allahu si n je Alagbara, Ologbon

[8] Dajudaju Awa ran o nise (pe ki o je) olujerii, oniroo-idunnu ati olukilo

[9] nitori ki e le ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojise Re, ati (nitori ki) e le se iranlowo fun (Ojise naa) ati nitori ki e le pataki re, ati nitori ki e le safomo fun (Allahu) ni owuro ati ni asale

[10] Dajudaju awon t’o n sadehun fun o (pe awon ko nii fese fee loju ogun), dajudaju Allahu ni won n sadehun fun. Owo Allahu wa loke owo won. Enikeni ti o ba tu adehun re, o tu u fun emi ara re. Enikeni ti o ba si mu adehun t’o se fun Allahu se, (Allahu) yoo fun un ni esan nla

[11] Awon olusaseyin fun ogun esin ninu awon Larubawa oko yoo maa wi fun o pe: "Awon dukia wa ati awon ara ile wa l’o ko airoju ba wa. Nitori naa, toro aforijin fun wa." Won n fi ahon won wi ohun ti ko si ninu okan won. So pe: "Ta ni o ni ikapa kini kan fun yin lodo Allahu ti O ba gbero (lati fi) inira kan yin tabi ti O ba gbero anfaani kan fun yin? Rara (ko si). Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[12] Rara (ki i se ise kan l’o di yin lowo lati lo jagun, amo) e ti lero pe Ojise ati awon onigbagbo ododo ko nii pada si odo ara ile won mo laelae. Won se iyen ni oso sinu okan yin. E si ro ero aburu. E si je ijo iparun

[13] Enikeni ti ko ba gba Allahu ati Ojise Re gbo, dajudaju Awa pese Ina sile de awon alaigbagbo

[14] Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. O n saforijin fun eni ti O ba fe. O si n je eni ti O ba fe niya. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun

[15] Awon olusaseyin fun ogun (Hudaebiyyah) n wi pe: "Nigba ti e lo sibi oro-ogun (Kaebar) nitori ki e le ri nnkan ko, won ja wa ju sile ki a ma le tele yin lo." (Awon olusaseyin wonyi) si n gbero lati yi oro Allahu pada ni. (Iwo Anabi) so pe: "Eyin ko gbodo tele wa. Bayen ni Allahu se so teletele." Won yo si tun wi pe: "Rara (ko ri bee), e n se keeta wa ni." Rara (eyin ko se keeta won, amo), won ki i gbo agboye (oro) afi die

[16] So fun awon olusaseyin fun ogun ninu awon Larubawa oko pe: "Won maa pe yin si awon eniyan kan ti won ni agbara ogun jija. E maa ja won logun tabi ki won juwo juse sile (fun ’Islam). Ti eyin ba tele ase (yii), Allahu yoo fun yin ni esan t’o dara. Ti eyin ba si gbunri pada gege bi e se gbunri siwaju, (Allahu) yo si fi iya eleta-elero je yin

[17] Ko si ese fun afoju, ko si ese fun aro, ko si si ese fun alaisan (ti won ko ba lo soju ogun). Enikeni ti o ba tele ti Allahu ati Ojise Re, (Allahu) yoo mu un wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Enikeni ti o ba si gbunri, O maa je e ni iya eleta-elero

[18] Dajudaju Allahu ti yonu si awon onigbagbo ododo nigba ti won n sadehun fun o labe igi (pe awon ko nii fese fee loju ogun). Nitori naa, (Allahu) mo ohun ti o wa ninu okan won. O si so ifokanbale kale fun won. O si san won ni esan isegun t’o sunmo

[19] ati awon oro ogun opolopo ti won yoo ri ko. Allahu n je Alagbara, Ologbon

[20] Ati pe Allahu sadehun awon oro ogun opolopo ti eyin yoo ri ko fun yin. O si tete mu eyi wa fun yin. O tun ko awon eniyan lowo ro fun yin nitori ki o le je ami kan fun awon onigbagbo ododo ati nitori ki O le fi ese yin rinle soju ona taara (’Islam)

[21] Ati omiran ti e o lagbara lori re, (amo ti) Allahu ti rokirika re. Allahu si n je Alagbara lori gbogbo nnkan

[22] Ti o ba je pe awon t’o sai gbagbo gbogun dide si yin ni, won iba peyin da (lati sagun fun yin). Leyin naa, won ko nii ri alaabo tabi alaranse kan

[23] Ise Allahu, eyi t’o ti sele siwaju (ni eyi). O o si nii ri iyipada fun ise Allahu (lori awon ota Re)

[24] Oun si ni Eni ti O ko won lowo ro fun yin. O si ko eyin naa lowo ro fun won ninu ilu Mokkah leyin igba ti O ti fi yin bori won. Allahu si n je Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[25] Awon (osebo) ni awon t’o sai gbagbo, ti won se yin lori kuro ni Mosalasi Haram, ti won tun de eran ore mole ki o ma le de aye re. Ti ki i ba se ti awon okunrin (ti won ti di) onigbagbo ododo ati awon obinrin (ti won ti di) onigbagbo ododo (ninu ilu Mokkah), ti eyin ko si mo won, ki eyin ma lo pa won, ki eyin ma lo fara ko ese lati ara won nipase aimo, (Allahu iba ti ko yin lowo ro fun won. Allahu ko yin lowo ro fun won se) nitori ki O le fi eni ti o ba fe sinu ike Re. Ti o ba je pe won wa ni otooto ni (onigbagbo ododo loto, alaigbagbo loto), Awa iba je awon t’o sai gbagbo ninu won ni iya eleta-elero

[26] (Ranti) nigba ti awon t’o sai gbagbo ko igbonara sinu okan won ni igbonara ti igba aimokan, Allahu si so ifokanbale kale fun Ojise Re ati awon onigbagbo ododo. O si je ki oro iberu (Re) wa pelu won; Won ni eto si i julo, awon ni won si ni in. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[27] Dajudaju Allahu ti so ala Ojise Re di ododo pe - ti Allahu ba fe - dajudaju eyin yoo wo inu Mosalasi Haram ni eni ifayabale. E maa fa irun ori yin; e maa ge irun (ori yin mole), e o si nii paya. Nitori naa, (Allahu) mo ohun ti eyin ko mo. Yato si iyen, O tun se isegun t’o sunmo (fun yin)

[28] (Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata. Allahu si to ni Elerii

[29] Muhammad ni Ojise Allahu. Awon t’o wa pelu re, won le mo awon alaigbagbo, alaaanu si ni won laaarin ara won. O maa ri won ni oludawote-orunkun ati oluforikanle (lori irun), ti won n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Allahu. Ami won wa ni oju won nibi oripa iforikanle. Iyen ni apejuwe won ninu Taorah ati apejuwe won ninu ’Injil, gege bi koro eso igi t’o yo ogomo re jade. Leyin naa, o nipon (o lagbara), o si duro gbagidi lori igi re. O si n jo awon agbe loju. (Allahu fi aye gba Anabi ati awon Sohabah re) nitori ki O le fi won se ohun ibinu fun awon alaigbagbo. Allahu sadehun aforijin ati esan nla fun awon t’o gbagbo, ti won si se awon ise rere ninu won

Àwọn Ìyàrá

Surah 49

[1] Eyin ti e gbagbo ni ododo, eyin ko gbodo gbawaju mo Allahu ati Ojise Re lowo. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo

[2] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se gbe ohun yin ga bori ohun Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam). Ki e si ma se fi ohun ariwo ba a soro gege bi apa kan yin se n fi ohun ariwo ba apa kan soro nitori ki awon ise yin ma baa baje, eyin ko si nii fura

[3] Dajudaju awon t’o n re ohun won nile lodo Ojise Allahu, awon wonyen ni awon ti Allahu ti gbidanwo okan won fun iberu (Re). Aforijin ati esan nla wa fun won

[4] Dajudaju awon t’o n pe o lati eyin awon yara, opolopo won ni ko se laakaye

[5] Ti o ba je pe dajudaju won se suuru titi o maa fi jade si won ni, iba dara julo fun won. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[6] Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti obileje kan ba mu iro kan wa ba yin, e se pelepele lati mo ododo (nipa oro naa) nitori ki e ma baa se awon eniyan kan ni suta pelu aimo. Leyin naa, ki e ma baa di alabaamo lori ohun ti e se

[7] Ki e si mo pe dajudaju Ojise Allahu wa laarin yin. Ti o ba je pe o n tele yin nibi opolopo ninu oro (t’o n sele) ni, dajudaju eyin iba ti ko o sinu idaamu. Sugbon Allahu je ki e nifee si igbagbo ododo. O se e ni oso sinu okan yin. O si je ki e korira aigbagbo, iwa buruku ati iyapa ase. Awon wonyen ni awon olumona

[8] (Eyi je) oore ajulo ati idera lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[9] Ti igun meji ninu awon onigbagbo ododo ba n ba ara won ja, e se atunse laaarin awon mejeeji. Ti okan ninu awon mejeeji ba si koja enu-ala lori ikeji, e ba eyi ti o koja enu-ala ja titi o fi maa seri pada sibi ase Allahu. Ti o ba si seri pada, e se atunse laaarin awon mejeeji pelu deede. Ki e si se eto. Dajudaju Allahu feran awon oluse-eto

[10] Omo iya (esin) ni awon onigbagbo ododo. Nitori naa, e satunse laaarin awon omo iya yin mejeeji. Ki e si beru Allahu nitori ki A le ke yin

[11] Eyin ti e gbagbo ni ododo, awon eniyan kan ko gbodo fi awon eniyan kan se yeye. O le je pe awon (ti won so di oniyeye) dara ju awon (t’o n se yeye). Awon obinrin kan (ko si gbodo fi) awon obinrin kan (se yeye). O le je pe awon (ti won so di oniyeye) dara ju awon (t’o n se yeye). E ma se bura yin. E ma pe’ra yin loriki buruku leyin igbagbo ododo. Enikeni ti ko ba ronu piwada, awon wonyen ni awon alabosi

[12] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e jinna si opolopo aroso. Dajudaju apa kan aroso ni ese. E ma se topinpin ara yin. Ki apa kan yin ma se soro apa kan leyin. Se okan ninu yin nifee si lati je eran-ara omo iya re t’o ti ku ni? E si korira re. E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

[13] Eyin eniyan, dajudaju Awa seda yin lati ara okunrin ati obinrin. A si se yin ni orile-ede orile-ede ati iran-iran nitori ki e le dara yin mo. Dajudaju alapon-onle julo ninu yin lodo Allahu ni eni t’o beru (Re) julo. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alamotan

[14] Awon Larubawa oko so pe: "A gbagbo ni ododo." So pe: "Eyin ko gbagbo ni ododo." Sugbon e so pe: "A gba ’Islam." niwon igba ti igbagbo ododo ko ti i wo’nu okan yin. Ti e ba tele (ase) Allahu ati Ojise Re, (Allahu) ko nii din kini kan ku fun yin ninu (esan) awon ise yin. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[15] Awon onigbagbo ododo ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, leyin naa ti won ko seyemeji, ti won si fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Awon wonyen, awon ni olododo

[16] So pe: "Se e maa ko Allahu ni esin yin ni?" Allahu si mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[17] Won n seregun lori re pe won gba ’Islam. So pe: "E ma fi ’Islam yin seregun lori mi.” Bee ni! Allahu l’O maa seregun lori yin pe O fi yin mona sibi igbagbo ododo ti e ba je olododo

[18] Dajudaju Allahu mo ikoko awon sanmo ati ile. Ati pe Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

Qāf

Surah 50

[1] Ƙof. (Allahu fi) al-Ƙur’an alapon-onle bura

[2] Sugbon won seemo nitori pe olukilo kan wa ba won lati aarin ara won. Awon alaigbagbo si wi pe: "Eyi ni ohun iyanu

[3] Se nigba ti a ba ti ku, ti a ti di erupe (ni a oo tun ji dide pada). Iyen ni idapada to jinna (si nnkan ti o le sele)

[4] Dajudaju A ti mo ohun ti ile n mu je ninu won. Tira (ise eda ) ti won n so si wa ni odo Wa

[5] Sibesibe won pe ododo (al-Ƙur’an) ni iro nigba ti o de ba won. Nitori naa, won ti wa ninu idaamu

[6] Se won ko wo sanmo oke won bi A ti se mo on pa ati (bi) A ti se e ni oso, ti ko si si alafo sisan kan lara re

[7] Ati pe ile, A te e perese. A si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu re. A si mu orisirisi irugbin t’o dara hu jade lati inu re

[8] (O je) ariwoye ati iranti fun gbogbo erusin to n seri pada (sibi ododo)

[9] A n so omi ibukun kale lati sanmo. A si n fi mu awon ogba oko ati awon eso ti won maa kaje hu jade

[10] (A tun mu) igi dabinu hu ga, ti awon eso ori re so jigbinni

[11] Arisiki ni fun awon eru (Allahu). A si n fi so oku ile di aye. Bayen ni ijade eda (lati inu saree yo se ri)

[12] Awon eniyan (Anabi) Nuh, awon eniyan Rass ati awon (eniyan) Thamud pe ododo niro siwaju won

[13] Ati awon ‘Ad, Fir‘aon ati awon omo iya (Anabi) Lut

[14] ati awon ara ’Aekah ati awon ijo Tubba‘u; gbogbo won pe awon Ojise ni opuro. Nitori naa, ileri Mi si di eto (lori won)

[15] Nje iseda akoko ko agara ba Wa bi? Rara, won wa ninu iyemeji nipa iseda (won) ni titun ni

[16] Dajudaju A seda eniyan. A si mo ohun ti emi re n so fun un. Awa si sunmo on ju isan orun re

[17] (Ranti) nigba ti (molaika) awon agboro-sile meji ba beresi gba oro (sile), ti okan jokoo si otun, ti okan jokoo si osi

[18] (Eni kan) ko si nii so oro kan ayafi ki eso kan wa pelu re (fun akosile re)

[19] Ati pe ipokaka iku yoo de lati fi ododo orun rinle. Iyen ni ohun ti iwo n sa fun

[20] Won a fon fere oniwo fun ajinde. Iyen ni ojo ileri naa

[21] Emi kookan yoo wa pelu oludari kan ati elerii kan (ninu awon molaika)

[22] Dajudaju iwo ti wa ninu igbagbera nibi eyi. A si ti si ebibo (oju) re kuro fun o bayii. Nitori naa, iriran re yoo riran kedere ni oni

[23] (Molaika) alabaarin re yoo so pe: "Eyi ni ohun ti n be ni odo mi (gege bi akosile ise re)

[24] E ju u sinu ina Jahanamo, gbogbo alaigbagbo olorikunkun

[25] oludena-ise rere, alakoyo, oniyemeji

[26] eni to mu olohun miiran mo Allahu. E ju u sinu iya lile

[27] (Esu) alabaarin re yoo wi pe: "Oluwa wa, emi ko ni mo si i lona, sugbon o ti wa ninu isina to jinna (si ododo) teletele

[28] (Allahu) yoo so pe: "E ma se sariyanjiyan lodo Mi. Mo kuku ti se ileri fun yin siwaju

[29] Won ko si le yi oro naa pada ni odo Mi. Emi ko si nii se abosi si awon eru Mi

[30] (Ranti) ojo ti A oo so fun ina Jahnamo pe: Sebi o ti kun?" O si maa so pe: "Sebi afikun tun wa

[31] Won maa sun Ogba Idera mo awon oluberu (Allahu). Ko si nii jinna (si won)

[32] Eyi ni ohun ti A n se ni adehun fun gbogbo oluronupiwada, oluso (ofin Allahu)

[33] Enikeni ti o ba paya Allahu ni ikoko, ti o tun de pelu okan to seri pada si odo Allahu (nipa ironupiwada)

[34] (A oo so fun won pe:) "E wo inu (Ogba Idera) pelu alaafia. Iyen ni ojo gbere

[35] Ohun ti won n fe wa ninu re. Alekun si tun wa ni odo Wa

[36] Meloo meloo ninu awon ijo ti A ti pare siwaju won. Won si ni agbara ju won lo. (Nigba ti iya de) won sa asala kiri ninu ilu. Nje ibusasi kan wa (fun won bi)

[37] Dajudaju iranti wa ninu iyen fun eni to ni okan tabi eni to fi eti sile, to wa nibe (pelu okan re)

[38] Dajudaju A seda awon sanmo, ile ati nnkan to wa laaarin awon mejeeji fun ojo mefa. Ko si re Wa rara (ambosibosi pe A oo sinmi ni ojo keje)

[39] Nitori naa, se suuru lori ohun ti won n wi. Ki o si se afomo pelu idupe fun Oluwa Re siwaju yiyo oorun ati wiwo (re)

[40] Ati pe ni oru ati ni eyin irun se afomo fun Un

[41] Ki o si teti si ojo ti olupepe yoo pepe lati aye kan t’o sunmo

[42] Ojo ti won yoo gbo igbe pelu ododo. Iyen ni ojo ijade eda (lati inu saree)

[43] Dajudaju Awa, Awa l’A n so eda di alaaye. A si n so o di oku. Odo Wa si ni abo eda

[44] (Ranti) ojo ti ile yoo faya perepere mo won lara, (ti won yoo maa) yara (jade lati inu ile). Iyen ni akojo t’o rorun fun Wa

[45] Awa nimo julo nipa ohun ti won n wi. Iwo ko si nii je won nipa (lati gbagbo). Nitori naa, fi al-Ƙur’an se iranti fun eni ti n paya ileri Mi

Àwọn Afẹ́fẹ́ Tí ń fẹ́

Surah 51

[1] (Allahu bura pelu) ategun t’o n tu erupe jade nile taara

[2] (O bura pelu) awon esujo t’o wuwo rinrin

[3] (O bura pelu) awon oko oju-omi t’o n rin pelu irorun

[4] (O bura pelu) awon molaika t’o n pin nnkan (ti O ti pin fun eda)

[5] Ododo ma ni ohun ti A n se ni adehun fun yin

[6] Ati pe dajudaju Ojo Esan maa sele

[7] (Allahu tun bura pelu) sanmo olosoo

[8] Dajudaju eyin wa lori oro t’o n takora won (nipa al-Ƙur’an)

[9] Eni ti won n se lori kuro nibi al-Ƙur’an ni eni ti Won ti se lori kuro nibe (lati inu Laohul-Mahfuth)

[10] Egbe ni fun awon opuro

[11] awon ni won wa ninu aimokan, awon onigbagbe

[12] ti won n beere igba ti Ojo Esan maa sele

[13] Ni ojo naa si ni won yoo maa fi Ina je won niya

[14] E to iya yin wo. Eyi ni nnkan ti e ti n wa pelu ikanju

[15] Dajudaju awon oluberu (Allahu) yoo wa ninu awon Ogba Idera pelu awon omi odo (ni isale re)

[16] Won yoo maa gba nnkan ti Oluwa won ba fun won. Dajudaju won ti je oluse-rere siwaju iyen

[17] Won maa n sun oorun die ninu oru

[18] Won maa n toro aforijin ni afemojumo

[19] Ninu dukia won, won ni ojuse ti won n se fun alagbe ati eni ti A se arisiki ni eewo fun

[20] Awon ami wa ni ori ile fun awon alamodaju

[21] Ninu emi ara yin gan-an (ami iyanu wa ninu re). Se e o riran ni

[22] Arisiki yin ati ohun ti A n se ni adehun fun yin wa ninu sanmo

[23] Nitori naa, Mo fi Oluwa sanmo ati ile bura, dajudaju ododo ni (oro naa) gege bi o se je ododo pe e n fenu soro

[24] Nje oro awon alejo (Anabi) ’Ibrohim, awon alapon-onle, ti de odo re

[25] (Ranti) nigba ti won wole to o wa, won si so pe: "Alaafia (fun o)." Oun naa so pe: "Alaafia (fun yin), eyin ajoji eniyan

[26] O lo si odo awon ara ile re, o si de pelu omo maalu oloraa (ayangbe)

[27] O gbe e sunmo odo won. O si so pe: "Se e o nii jeun ni

[28] Nigba naa, o ni ipaya won ninu okan. Won so pe: "Ma se paya." Won si fun un ni iro idunnu nipa bibi omokunrin onimo kan

[29] Nigba naa, iyawo re si bere igbe, o si gbara re loju, o so pe: "Arugbo, agan (ma ni mi)

[30] Won so pe: "Bayen ni Oluwa re so. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo

[31] (Anabi ’Ibrohim) so pe: "Ki tun ni oro ti e ba wa, eyin Ojise

[32] Won so pe: "Dajudaju Won ran wa nise si ijo elese ni

[33] nitori ki a le fi okuta amo (sisun) ranse si won

[34] Won ti fami si i lara lodo Oluwa re fun awon alakoyo

[35] Nitori naa, A mu awon t’o je onigbagbo ododo jade kuro ninu (ilu naa)

[36] A o si ri ninu (ilu naa) tayo ile kan t’o je ti awon musulumi

[37] A si fi ami kan sile ninu (ilu naa) fun awon t’o n paya iya eleta-elero

[38] (Ami tun wa) lara (Anabi) Musa. Nigba ti A fi eri ponnbele ran an nise si Fir‘aon

[39] Sugbon (Fir‘aon) gbunri pelu awon omo ogun re. O si wi pe: "Opidan tabi were kan (niyi)

[40] Nitori naa, A mu oun ati awon omo ogun re. A si ju won sinu agbami odo nigba ti o je alabuku

[41] (Ami tun wa) lara ijo ‘Ad. (Ranti) nigba ti A ran ategun iparun si won

[42] ko fi kini kan to fe si lara sile bee afi ko so o di bi eso rirun tuutu

[43] (Ami tun wa) lara ijo Thamud. (Ranti) nigba ti A so fun won pe: "E jaye fun igba die na

[44] Won segberaga si ase Oluwa won. Nitori naa, igbe iparun mu won; won si n wo boo

[45] Won ko le dide naro. Won ko si le ran ara won lowo

[46] Ati ijo Nuh ti o siwaju (won), dajudaju Awa si ni olugbooro

[47] Ati pe sanmo, A mo on (si oke yin) pelu agbara. Dajudaju Awa si ni olugbooro

[48] Ati ile, A se e ni ite. Awon olutele-sile si dara

[49] Ati pe gbogbo nnkan ni A seda ni orisi meji-meji nitori ki e le lo iranti

[50] Nitori naa, e sa lo si odo Allahu (nipa ironupiwada). Dajudaju emi ni olukilo ponnbele fun yin lati odo Re

[51] E ma se mu olohun miiran mo Allahu. Dajudaju emi ni olukilo ponnbele fun yin lati odo Re

[52] Bayen ni (oro se ri)! Ojise kan ko wa ba awon t’o siwaju won afi ki won wi pe: "Opidan tabi were ni

[53] Se won so asoole nipa re laaarin ara won ni? Rara o! Ijo olutayo-enu-ala ni won ni

[54] Nitori naa, seri kuro lodo won na. Iwo ki i se alabuku

[55] Seranti nitori pe, dajudaju iranti maa wulo fun awon onigbagbo ododo

[56] Ati pe Emi ko seda alujannu ati eniyan bi ko se pe ki won le josin fun Mi

[57] Emi ko gbero arisiki kan lati odo won. Emi ko si gbero pe ki won maa bo Mi

[58] Dajudaju Allahu, Oun ni Olupese, Alagbara lile

[59] Dajudaju ipin iya ti o maa je awon t’o sabosi (wonyi) ni iru ipin iya ti o je ijo elese (iru) won. Nitori naa, ki won ma se kan Mi loju (nipa iya won)

[60] Nitori naa, egbe ni fun awon t’o sai gbagbo ni ojo won ti A n se ni adehun fun won

Òkè

Surah 52

[1] (Allahu bura pelu) apata Tur

[2] (O tun bura pelu) Tira ti won ko sile

[3] sinu takada ti won te sile

[4] (O tun bura pelu) Ile Abewo naa

[5] (O tun bura pelu) aja ti won gbe soke (iyen, sanmo)

[6] (O tun bura pelu) agbami odo ina

[7] Dajudaju iya Oluwa re maa sele

[8] Ko si oludena kan fun un

[9] (O maa sele) ni ojo ti sanmo maa mi titi taara

[10] Awon apata si maa rin lo taara (bi eruku afedanu)

[11] Ni ojo yen, egbe ni fun awon olupe-ododo-niro

[12] awon ti won wa ninu isokuso, ti won n sere

[13] (Ranti) ojo ti won yoo ti won lo sinu ina Jahanamo ni itikuti

[14] Eyi ni Ina naa ti e n pe niro

[15] Se idan ni eyi ni tabi e o riran

[16] E wo inu re lo. E fara da a tabi e o fara da a, bakan naa ni fun yin. Ohun ti e n se nise ni A oo fi san yin ni esan

[17] Dajudaju awon oluberu (Allahu) maa wa ninu awon Ogba ati idera

[18] Won yoo maa je igbadun pelu ohun ti Oluwa won fun won. Ati pe (Allahu) yoo so won ninu iya ina Jehim

[19] E maa je, e maa mu ni gbedemuke nitori ohun ti e n se nise

[20] Won yoo rogboku sori awon ibusun ti won to ni owoowo. A si maa fun won ni awon iyawo eleyinju ege

[21] Ati pe awon t’o gbagbo ni ododo, ti awon aromodomo won tun tele won ninu igbagbo ododo, A maa da awon aromodomo won po mo won. A o si nii din kini kan ku ninu ise won. Eni kookan ni oniduuro fun ohun t’o se nise

[22] A maa fun won ni alekun eso ati eran ti won nifee si

[23] Won yo si maa gba ife oti mu laaarin ara won ninu Ogba Idera. Ko si oro isokuso ati iwa ese ninu Ogba Idera

[24] Awon omo-odo won yo si maa lo bo laaarin won. (Won) da bi aluuulu afipamo

[25] Apa kan won yoo doju ko apa kan, won yo si maa beere oro lowo ara won

[26] Won yoo so pe: "Dajudaju teletele awa je olupaya laaarin awon eniyan wa

[27] Sugbon Allahu saanu wa. O si la wa nibi iya Ina

[28] Dajudaju awa maa n pe E teletele. Dajudaju Allahu, Oun ni Oloore, Asake-orun

[29] Nitori naa, seranti. Iwo ki i se adabigba tabi were lori idera Oluwa re

[30] Tabi won n wi pe: "Elewi kan ti a n reti iku re ni

[31] So pe: "E maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti

[32] Tabi opolo won n pa won lase eyi ni? Tabi ijo alakoyo ni won ni

[33] Tabi won n wi pe: "O da (al-Ƙur’an) hun funra re ni." Rara o, won ko gbagbo ni

[34] Ki awon naa mu oro kan bi iru re wa ti won ba je olododo

[35] Tabi won seda won lai si Aseda? Tabi awon ni won seda ara won ni

[36] Tabi awon ni won seda awon sanmo ati ile? Rara o, won ko mamo daju ni

[37] Tabi lodo won ni awon apoti oro Oluwa re wa? Tabi awon ni olubori

[38] Tabi won ni akaba ti won n fi gboro (ninu sanmo ni)? Ki olugboro won mu eri ponnbele wa

[39] Tabi awon omobinrin ni tiRe, awon omokunrin si ni tiyin

[40] Tabi o n beere owo-oya kan lodo won, ni gbese fi wo won lorun

[41] Tabi imo ikoko wa lodo won, ti won si n ko o sile

[42] Tabi won n gbero ete kan ni? Nigba naa, awon t’o sai gbagbo, awon l’o maa f’ori ko ete

[43] Tabi won ni olohun kan leyin Allahu ni? Mimo ni fun Allahu tayo nnkan ti won n fi sebo si I

[44] Ti won ba si ri apa kan ninu sanmo t’o ya lule, won a wi pe: "Esujo regede ni (won ko nii gbagbo)

[45] Nitori naa, fi won sile titi won yoo fi ba ojo won ti won maa pa won sinu re pade

[46] Ojo ti ete won ko nii fi kini kan ro won loro. A o si nii ran won lowo

[47] Ati pe dajudaju iya kan n be fun awon t’o sabosi yato si (iya orun) yen, sugbon opolopo won ni ko mo

[48] Se suuru fun idajo Oluwa Re, dajudaju iwo wa ni ojuto Wa. Ki o si se afomo pelu idupe fun Oluwa re nigba ti o ba n dide naro (fun irun kiki)

[49] Ati ni ale (nigba ti) awon irawo ba kuro nita tan, safomo fun Un

Ìràwọ̀

Surah 53

[1] (Allahu bura pelu) irawo nigba ti o ba jabo

[2] Eni yin ko sina, ko si sonu

[3] Ati pe ko nii soro ife-inu

[4] Ko nii so ohun kan tayo imisi ti A fi ranse si i

[5] Alagbara (iyen, molaika Jibril) l’o ko o ni imo (al-Ƙur’an)

[6] O ni alaafia t’o peye. Nitori naa, o duro wamuwamu

[7] nigba ti o wa ninu ofurufu loke patapata

[8] Leyin naa, o sun mo (Anabi). O si sokale (to o wa)

[9] (Alafo aarin awon mejeeji) si to iwon orun ofa meji, tabi ki o kere (si iyen)

[10] Allahu si fun erusin Re ni imisi t’O fun un

[11] Okan (Anabi) ko paro ohun t’o ri

[12] Se e oo ja a niyan nipa ohun t’o ri ni

[13] Ati pe dajudaju o ri i nigba keji Allahu (subhanahu wa ta'ala) ni o ri bi o tile je pe igun yii fi kun un pe okan l’o fi ri Allahu bii oro ti o todo Omo ‘Abbas (rodiyallahu 'anhu) wa pe “Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) fi okan re ri Allahu ni.” Iyen ni pe

[14] nibi igi sidirah al-Muntaha

[15] nitosi re ni Ogba Ibugbe (gbere) wa

[16] (Ranti) nigba ti ohun t’o bo igi Sidirah bo o mole

[17] Oju (Anabi) ko ye, ko si tayo enu-ala

[18] Dajudaju o ri ninu awon ami Oluwa re, t’o tobi julo

[19] E so fun mi nipa orisa Lat ati orisa ‘Uzza

[20] ati Monah, orisa keta miiran

[21] Se omokunrin ni tiyin, omobinrin si ni tiRe

[22] Ipin abosi niyen nigba naa

[23] (Awon oruko orisa wonyen) ko si je kini kan bi ko se awon oruko kan ti eyin ati awon baba yin fi so (awon orisa yin funra yin). Allahu ko si so eri oro kan kale nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso ati ohun ti emi (won) n fe. Imona kuku ti de ba won lati odo Oluwa won

[24] Tabi ti eniyan ni nnkan t’o ba n fe

[25] Ti Allahu si ni orun ati aye

[26] Ati pe meloo meloo ninu awon molaika t’o wa ninu awon sanmo, ti isipe won ko nii ro won loro kini kan ayafi leyin igba ti Allahu ba yonda fun eni ti O ba fe, ti O si yonu si

[27] Dajudaju awon ti ko ni igbagbo ododo ninu Ojo Ikeyin, awon ni won n fun awon molaika ni oruko obinrin

[28] Ko si imo kan fun won nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si nii roro kini kan lara ododo

[29] Nitori naa, seri kuro ni odo eni t’o keyin si iranti Wa, ti ko si gbero kini kan afi isemi aye

[30] Iyen ni odiwon (ati opin) imo won. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa eni t’o mona

[31] Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile nitori ki O le san awon t’o se ise aburu ni esan ohun ti won se nise ati nitori ki O le san awon t’o se ise rere ni esan rere

[32] Awon t’o n jinna si ese nla nla ati iwa ibaje ayafi awon ese peepeepe, dajudaju Oluwa re gbooro ni aforijin. O nimo julo nipa yin nigba ti O seda yin lati inu ile ati nigba ti e wa ni ole ninu awon ikun iya yin. Nitori naa, e ma se fora yin mo. O nimo julo nipa eni t’o beru (Re)

[33] So fun mi nipa eni t’o gbunri (kuro nibi ododo)

[34] ti o fi die tore, ti o si di iyoku mowo

[35] Se imo ikoko wa ni odo re, ti o si n ri i (pe elomiiran l’o ma ba oun jiya lorun)

[36] Tabi won ko fun un ni iro ohun t’o wa ninu tira (Anabi) Musa ni

[37] ati (tira Anabi) ’Ibrohim, eni t’o mu (ofin Allahu) se

[38] pe dajudaju eleru-ese kan ko nii ru eru-ese elomiiran

[39] Ati pe ko si kini kan fun eniyan afi ohun t’o se nise

[40] Ati pe dajudaju ise re, laipe won maa fi han an

[41] Leyin naa, won maa san an ni esan re, ni esan t’o kun julo

[42] Ati pe dajudaju odo Oluwa re ni opin (irin-ajo eda)

[43] Dajudaju Oun l’O n pa (eda) ni erin. O si n pa (eda) ni ekun

[44] Dajudaju Oun l’O n so (eda) di oku. O si n so (eda) di alaaye

[45] Dajudaju Oun l’O da eda ni orisi meji, okunrin ati obinrin

[46] lati ara ato nigba ti won ba da a sinu apoluke

[47] Dajudaju Oun l’O maa se iseda ikeyin fun ajinde

[48] Dajudaju Oun l’O n se pupo, O si n se kekere (oore fun eda)

[49] Dajudaju Oun si ni Oluwa irawo Si‘ro (ti won so di orisa)

[50] Dajudaju Oun l’O pa iran ‘Ad re, awon eni akoko

[51] ati iran Thamud, ko si se won ku

[52] ati ijo Nuh t’o siwaju (won), dajudaju won je alabosi julo, won si tayo enu-ala julo

[53] ati ilu ti won dawo (ilu Anabi Lut) t’O ye lule (lati oke)

[54] Ohun t’o bo won mole bo won mole

[55] Nitori naa, ewo ninu idera Oluwa re ni iwo (eniyan) n ja niyan

[56] Eyi ni ikilo kan ninu awon ikilo akoko

[57] Ohun t’o sunmo sunmo

[58] Leyin Allahu, ko si eni t’o le safi han (Akoko naa)

[59] Se oro yii l’o n se yin ni kayefi

[60] E n rerin-in, e o si sunkun

[61] Afonu-fora ni yin

[62] Nitori naa, e fori kanle fun Allahu, ki e josin (fun Un)

Òṣùpá

Surah 54

[1] Akoko naa sunmo. Osupa si la peregede (si meji)

[2] Ti won ba ri ami kan, won maa gbunri. Won yo si wi pe: "Idan kan (t’o lagbara) t’o maa lo ni

[3] Won pe e niro. Won si tele ife-inu won. Gbogbo ise eda si maa jokoo ti i lorun

[4] Dajudaju eyi ti won fi ohun lile ko wa ninu awon iro t’o de ba won

[5] Ijinle oye t’o peye ni; sugbon awon ikilo naa ko ro won loro

[6] Seri kuro ni odo won. Ni ojo ti olupepe yoo pepe fun kini kan ti emi korira (iyen, Ajinde)

[7] Oju won maa wale ni ti abuku. Won yo si maa jade lati inu saree bi eni pe esu ti won fonka sita ni won

[8] Won yo si maa yara lo si odo olupepe naa. Awon alaigbagbo yo si wi pe: "Eyi ni ojo isoro

[9] Ijo (Anabi) Nuh pe ododo niro siwaju won. Nigba naa, won pe erusin Wa ni opuro. Won si wi pe: "Were ni." Won si ko fun un pelu ohun lile. won fi ohun lile ko ododo sile fun Anabi Nuh ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ni kiko alesa-seyin fun won nipase siso oro buruku si i hihale mo on

[10] Nitori naa, o pe Oluwa re pe: "Dajudaju won ti bori mi. Ran mi lowo

[11] Nitori naa, A si awon ilekun sanmo sile pelu omi t’o lagbara

[12] A tun mu awon odo seyo lori ile. Omi (sanmo) pade (omi ile) pelu ase ti A ti ko (le won lori)

[13] A si gbe (Anabi) Nuh gun oko onipako, oko elesoo

[14] t’o n rin (lori omi) loju Wa. (O je) esan fun eni ti won tako

[15] Dajudaju A fi sile ni ami. Nje oluranti wa bayii bi

[16] Bawo ni iya Mi ati ikilo Mi ti ri na (lara won)

[17] Dajudaju A se al-Ƙur’an ni irorun fun sise iranti. Nje oluranti wa bayii bi

[18] Iran ‘Ad pe ododo niro. Bawo ni iya Mi ati ikilo Mi ti ri na (lara won)

[19] Dajudaju Awa ran ategun lile si won ni ojo buruku kan t’o n te siwaju

[20] O n fa awon eniyan jade bi eni pe kukute igi ope ti won fa tu tegbotegbo ni won

[21] Bawo ni iya Mi ati ikilo Mi ti ri na (lara won)

[22] Dajudaju A se al-Ƙur’an ni irorun fun sise iranti. Nje oluranti wa bayii bi

[23] Ijo Thamud pe awon ikilo niro

[24] Won wi pe: "Se abara kan, eni kan soso ninu wa ni a oo maa tele. (Bi o ba ri bee) nigba naa dajudaju awa ti wa ninu isina ati iya

[25] Se oun ni won so iranti kale fun laaarin wa? Rara o, opuro onigbeeraga ni

[26] Ni ola ni won yoo mo ta ni opuro onigbeeraga

[27] Dajudaju Awa maa ran abo rakunmi si won; (o maa je) adanwo fun won. Nitori naa, maa wo won niran na, ki o si se suuru

[28] Ki o si fun won ni iro pe dajudaju pipin ni omi laaarin won. Gbogbo ipin omi si wa fun eni ti o ba kan lati wa si odo

[29] Nigba naa ni won pe eni won. O wa ona lati mu (rakunmi naa mole). O si pa a

[30] Bawo ni iya Mi ati ikilo Mi ti ri na (lara won)

[31] Dajudaju Awa ran igbe kan soso si won. Won si da bi igi koriko gbigbe

[32] Dajudaju A se al-Ƙur’an ni irorun fun sise iranti. Nje oluranti wa bayii bi

[33] Ijo Lut pe awon ikilo niro

[34] Dajudaju Awa fi okuta ina ranse si won afi ara ile Lut, ti A gbala ni asiko saari

[35] (O je) ike kan lati odo Wa. Bayen ni A se n san esan fun eni t’o ba dupe (fun Wa)

[36] O kuku fi igbamu Wa se ikilo fun won, sugbon won ja awon ikilo niyan

[37] Won kuku lakaka lodo re lati ba awon alejo re sebaje. Nitori naa, A fo oju won. E to iya Mi ati ikilo Mi wo

[38] Ati pe dajudaju iya gbere ni won mojumo sinu re ni owuro kutukutu

[39] Nitori naa, e to iya Mi ati ikilo Mi wo

[40] Dajudaju A se al-Ƙur’an ni irorun fun sise iranti. Nje oluranti wa bayii bi

[41] Dajudaju awon ikilo de ba awon eniyan Fir‘aon

[42] Won pe awon ayah Wa niro, gbogbo re patapata. A si gba won mu ni igbamu (ti) Alagbara, Olukapa (n gba eda mu)

[43] Se awon alaigbagbo (ninu) yin l’o loore julo si awon wonyen (ti won ti pare bo seyin) ni tabi eyin ni imoribo kan ninu ipin-ipin Tira (pe eyin ko nii jiya)

[44] Tabi won n wi pe: "Gbogbo wa ni a oo ranra wa lowo lati bori (Ojise)

[45] A maa fo akojo naa logun. Won si maa fese fee loju ogun

[46] Amo sa, Akoko naa ni ojo adehun won. Akoko naa buru julo. O si koro julo

[47] Dajudaju awon elese wa ninu isina (nile aye, won yo si wa ninu) Ina jijo (ni orun)

[48] Ni ojo ti A oo doju won dele wo inu Ina, (A o si so pe): E to ifowoba Ina wo

[49] Dajudaju A seda gbogbo nnkan pelu kadara

[50] Ase Wa (fun mimu nnkan be) ko tayo (ase) eyo kan soso gege bi iseju

[51] Ati pe dajudaju A ti pa awon iru yin re. Nje oluranti wa bayii bi

[52] Gbogbo nnkan ti won se nise si wa ninu ipin-ipin tira

[53] Ati pe gbogbo nnkan kekere ati nnkan nla (ti won se) wa ni akosile

[54] Dajudaju awon oluberu (Allahu) yoo wa ninu awon Ogba (Idera) pelu awon odo (t’o n san ni isale re)

[55] Ni ibujokoo ododo nitosi Oba Alagbara Olukapa

Oloore Ọ̀fẹ́

Surah 55

[1] Ajoke-aye

[2] O fi imo al-Ƙur’an mo (eni ti O fe)

[3] O seda eniyan

[4] O si fi alaye (oro siso) mo on

[5] Oorun ati osupa (n rin) fun isiro (ojo aye)

[6] Awon itakun ile ati igi n fori kanle (fun Allahu)

[7] Ati sanmo, Allahu gbe e soke. O si fi osuwon ofin deede lele (fun eda)

[8] pe ki e ma se tayo enu-ala nibi osuwon

[9] E gbe osuwon naa duro pelu dogbadogba. Ki e si ma se din osuwon ku

[10] Ile, (Allahu) te e sile fun awon eda

[11] Eso ati dabinu alapo wa lori (ile)

[12] Ati eso koro onipoporo ati elewe dudu (wa lori ile)

[13] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[14] (Allahu) seda eniyan lati ara amo gbigbe t’o n dun kokoko bi ikoko amo

[15] O si seda alujannu lati ara ahon ina ti ko ni eefin

[16] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[17] Oluwa ibuyo oorun mejeeji ati ibuwo oorun mejeeji

[18] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[19] (Allahu) mu odo meji (odo oniyo ati odo aladun) san pade ara won

[20] Gaga kan si wa laaarin awon mejeeji ti won ko si le tayo enu-ala (re laaarin ara won)

[21] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[22] Okuta oniyebiye ati ileke iyun n jade ninu awon (odo) mejeeji naa

[23] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[24] Ti (Allahu) ni awon oko oju-omi gogoro t’o n rin ninu agbami odo (ti won da) bi apata giga

[25] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[26] Gbogbo eni t’o wa lori ile maa tan

[27] Oju Oluwa re, Atobi, Alapon-onle si maa wa titi laelae

[28] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[29] Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile n beere (nnkan) lodo Re; O si wa lori ise lojoojumo

[30] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[31] A oo mu tiyin gbo (lojo esan), eyin eniyan ati alujannu

[32] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[33] Eyin awujo alujannu ati eniyan, ti e ba lagbara lati sa jade ninu awon agbegbe sanmo ati ile, e sa jade. E o le sa jade afi pelu agbara

[34] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[35] Won maa ju eta-para ina ati eta-para ide le eyin mejeeji lori, eyin mejeeji ko si le ran’ra yin lowo

[36] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[37] Nitori naa, nigba ti sanmo ba faya perepere, o si maa pon wa we bi epo pupa

[38] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[39] Nitori naa, ni ojo yen Won o nii bi eniyan ati alujannu kan leere nipa ese re; (o ti wa ni akosile ni odo Wa)

[40] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[41] Won maa mo awon elese pelu ami ara won. Won si maa fi aaso ori ati ese gba won mu

[42] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[43] Eyi ni ina Jahanamo ti awon elese n pe niro

[44] Won yoo maa rin lo rin bo laaarin Ina ati omi t’o gbona pari

[45] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[46] Ogba Idera meji n be fun eni t’o ba paya iduro re niwaju Oluwa re

[47] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[48] (Awon Ogba Idera mejeeji ni) awon eka igi gigun

[49] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[50] Odo meji t’o n san wa ninu ogba mejeeji

[51] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[52] Orisi meji meji ni eso kookan t’o wa ninu ogba mejeeji

[53] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[54] Won yoo rogboku lori ite, ti awon ite inu re je aran t’o nipon. Awon eso ogba mejeeji si wa ni arowoto

[55] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[56] Awon obinrin ti ki i wo okunrin miiran wa ninu Ogba Idera. Eniyan ati alujannu kan ko si fowo kan won ri siwaju won

[57] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[58] Won da bii ileke segi ati ileke iyun

[59] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[60] Nje esan miiran wa fun sise rere bi ko se (esan) rere

[61] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[62] Ogba meji kan tun n be yato si meji (akoko yen)

[63] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[64] Alawo eweko (ni Ogba mejeeji naa)

[65] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[66] Awon odo meji t’o n tu omi jade lai dawo duro wa (ninu ogba mejeeji naa)

[67] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[68] Eso ipanu, dabinu ati eso rumon wa ninu ogba mejeeji

[69] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[70] Awon obinrin rere, arewa wa ninu awon Ogba Idera

[71] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[72] Awon eleyinju-ege kan (ni won), ti A fi pamo sinu ile-oso

[73] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[74] Eniyan ati alujannu kan ko fowo kan won ri siwaju won

[75] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[76] Won yoo rogboku lori awon timutimu alawo eweko ati ite t’o dara

[77] Nitori naa, ewo ninu awon idera Oluwa eyin eniyan ati alujannu ni e maa pe niro

[78] Ibukun ni fun oruko Oluwa re, Atobi, Alapon-onle

Dídájú

Surah 56

[1] Nigba ti Isele (Ajinde) ba sele

[2] ko si iro kan nipa isele re-E

[3] o maa mu (awon kan) wale (sinu Ina), o si maa gbe (awon kan) soke (ninu Ogba Idera)

[4] Nigba ti won ba mi ile titi ni mimititi

[5] ati nigba ti Won ba fo awon apata ni fifo womuwomu

[6] won si maa di eruku afedanu - E

[7] eyin si maa je orisi meta

[8] ijo osi ati ijo asiwaju. Amo ninu surah al-Balad; 90:18-19 ati surah az-Zalzalah; 99:6-8 Allahu (subhanahu wa ta'ala) pin won si ijo meji. Ijo meji kuku ni gbogbo eda ni orun 8 Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun

[9] Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi

[10] Awon asiwaju si ni awon asiwaju

[11] Awon wonyen ni alasun-unmo (Allahu)

[12] ninu Ogba Idera

[13] Won po ninu awon eni akoko

[14] Won si kere ninu awon eni Ikeyin

[15] (Won yoo wa) lori ite ti won fi goolu hun

[16] Won yoo rogboku sori re, won si maa doju kora won

[17] Awon odokunrin ti ko nii darugbo yo si maa lo bo laaarin won

[18] pelu awon ife omi, ohun iromi fenfe ati ife oti aladun

[19] Ko nii fo won lori; ko si nii mu won hunrira

[20] Eso ti won yoo maa sesa ninu re (tun wa fun won)

[21] Ati eran eye, eyi ti won n fe (yo wa fun won)

[22] Awon obinrin eleyinju ege (tun wa fun won)

[23] Won da bi okuta olowo-iyebiye ti won fi pamo

[24] (Iwonyi ni) esan fun ohun ti won n se nise

[25] Won ko nii gbo isokuso ati oro ese ninu Ogba Idera

[26] Ayafi oro alaafia, alaafia

[27] Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun

[28] (Won yoo wa) ni idi igi ti ko ni egun

[29] ati ogede t’o so jigbinni

[30] ati iboji t’o gbooro

[31] ati omi t’o n san lai dawo duro

[32] ati opolopo eso

[33] ti ko nii ja (ni odo won), ko si nii deewo (fun won)

[34] (Won maa wa lori) ite ti won gbe soke

[35] Dajudaju Awa tun (awon obinrin won) da ni eda otun

[36] A si se won ni wundia

[37] ololufe oko. Won si dogba ni ojo ori

[38] (Won wa) fun awon ero owo otun

[39] Won po ninu awon eni akoko

[40] Won tun po ninu awon eni Ikeyin

[41] Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi

[42] (Won yoo wa) ninu ategun gbigbona ati omi gbigbona

[43] ati ni abe iboji eleeefin dudu

[44] ko tutu, ko si dara

[45] Dajudaju won ti je onigbedemuke siwaju iyen

[46] Won si maa n sorikunkun lori ese nla

[47] Won si maa n wi pe: "Se nigba ti a ba di oku, ti a si di erupe ati egungun, nje Won yoo tun gbe wa dide ni

[48] Se ati awon baba wa, awon eni akoko

[49] So pe: "Dajudaju awon eni akoko ati awon eni Ikeyin

[50] dajudaju A oo ko won jo papo ni akoko ojo kan ti A ti mo

[51] Leyin naa, dajudaju eyin olusina, olupe-ododo-niro

[52] dajudaju eyin maa je ninu igi zaƙƙum (igi iwo)

[53] Ikun yin si maa kun bamubamu fun (jije) igi naa

[54] Eyin yo si maa mu omi gbigbona le e lori

[55] Eyin yoo maa mu un ni imumi rakunmi ti ongbe n gbe

[56] Eyi ni nnkan alejo won ni Ojo esan

[57] Awa l’A seda yin. Ki ni ko je ki e gbagbo lododo

[58] E so fun Mi nipa ato ti e n da jade (sinu apoluke)

[59] se eyin le seda re ni tabi Awa l’A seda re

[60] Awa l’A yan kadara (ojo) iku fun gbogbo yin. Awa ko si le kagara

[61] lati fi iru yin paaro yin, ki a si tun yin da sinu ohun ti e ko mo

[62] E kuku mo iseda akoko, e o se lo iranti

[63] E so fun Mi nipa nnkan ti e n gbin sinu ile

[64] se eyin l’e n je ki o hu jade ni tabi Awa l’A n je ki o hu jade

[65] Ti A ba fe ni, Awa iba so o di gbigbe, eyin yo si maa seemo (ti e oo maa ka abamo)

[66] (Eyin yo si wi pe:) "Dajudaju awa ti di onigbese

[67] (Awon miiran yo si wi pe:) "Rara o! Won se ikore oko ni eewo fun wa ni

[68] E so fun mi nipa omi ti e n mu

[69] se eyin l’e n so o kale lati inu esujo ni tabi Awa l’A n so o kale

[70] Ti A ba fe ni, Awa iba se e ni omi t’o moro. E o se maa dupe

[71] E so fun Mi nipa ina ti e n da

[72] se eyin l’e seda igi re ni tabi Awa ni Aseda

[73] Awa se ina aye ni iranti (fun Ina orun) ati nnkan elo fun awon onirin-ajo

[74] Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi

[75] Mo n bura pelu awon ibuso irawo

[76] Dajudaju ibura nla ni, ti e ba mo

[77] Dajudaju (al-Ƙur’an) ni nnkan kike alapon-onle

[78] (t’o wa) ninu Tira aabo (ninu Laohul-Mahfuth)

[79] Ko si eni to le fowo kan an (ni odo Allahu) afi awon eni mimo (iyen, awon molaika)

[80] Won so al-Ƙur’an kale lati odo Oluwa gbogbo eda

[81] Nitori naa, se oro (al-Ƙur’an) yii l’e n pe niro

[82] E si n so idupe arisiki yin di pe dajudaju e n pe ododo niro

[83] Ki ni o maa ti ri (fun yin) nigba ti emi (yin) ba de ona ofun

[84] ti eyin yo si maa woran nigba yen

[85] Awa si sunmo on ju eyin lo, sugbon eyin ko riran

[86] Eyin ko se je eni ti A o nii gbesan lara re

[87] ki e si da (emi ti o fe bo) pada, ti e ba je olododo

[88] Ni ti eni ti o ba wa ninu awon alasun-unmo (Wa)

[89] isinmi, ese t’o dara ati Ogba Idera (ni tire)

[90] Ni ti eni ti o ba wa ninu awon ero owo otun

[91] alaafia ni fun o laaarin awon ero owo otun

[92] Ni ti eni ti o ba wa ninu awon olupe-ododo-niro, awon olusina

[93] nnkan alejo (won) ni omi gbigbona

[94] ati wiwo inu ina Jehim

[95] Dajudaju eyi, ohun ni ododo t’o daju

[96] Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi

Irìn

Surah 57

[1] Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon

[2] TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oun ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[3] Oun ni Akoko ati Ikeyin. O han (pelu ami bibe Re). O si pamo (fun gbogbo oju nile aye). Oun ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[4] Oun ni Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O mo nnkan t’o n wo inu ile ati nnkan t’o n jade lati inu re, ati nnkan t’o n sokale lati inu sanmo ati nnkan t’o n gunke sinu re. Ati pe O wa pelu yin ni ibikibi ti e ba wa (pelu imo Re). Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[5] TiRe ni ijoba awon sanmo ati ile. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

[6] O n ti oru bo inu osan. O si n ti osan bo inu oru. Oun si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda

[7] E gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Ki e si na ninu ohun ti O fi yin se arole lori re. Nitori naa, awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si nawo (si oju ona esin), esan t’o tobi wa fun won

[8] Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii gba Allahu gbo ni ododo? Ojise si n pe yin nitori ki e le gba Oluwa yin gbo. Allahu si ti gba adehun lowo yin, ti eyin ba je onigbagbo ododo

[9] Oun ni Eni t’O n so awon ayah t’o yanju kale fun erusin Re nitori ki o le mu yin kuro ninu awon okunkun wa sinu imole. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun fun yin

[10] Ki ni o mu yin ti eyin ko fi nii nawo fun esin Allahu? Ti Allahu si ni ogun awon sanmo ati ile. Eni ti o nawo siwaju sisi ilu Mokkah, ti o tun jagun esin, ko dogba laaarin yin (si awon miiran). Awon wonyen ni esan won tobi julo si ti awon t’o nawo leyin igba naa, ti won tun jagun esin. Eni kookan si ni Allahu s’adehun esan rere fun. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[11] Ta ni eni ti o maa ya Allahu ni dukia t’o dara, O si maa sadipele re fun un. Esan alapon-onle si tun wa fun un

[12] Ni ojo ti o maa ri awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin, ti imole won yoo maa tan niwaju won ati ni owo otun won, (A oo so pe:) "Iro idunnu yin ni oni ni awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re." Olusegbere ni yin ninu re. Iyen si ni erenje nla

[13] Ni ojo ti awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumi lobinrin yoo wi fun awon t’o gbagbo pe: "E duro fun wa na, e je ki a mu ninu imole yin." A oo so fun won pe: "E pada s’eyin yin, ki e lo mu imole.” Won si maa fi ogiri kan, t’o ni ilekun saarin won. Ike wa ninu re, iya si wa ni ode re ni owo iwaju re

[14] (Awon sobe-selu musulumi) yoo pe (awon onigbagbo ododo) pe: "Se awa ko ti wa pelu yin ni?" Won so pe: "Rara, sugbon e ko iyonu ba emi ara yin (nipa isobe-selu), e reti iparun (wa), e si siyemeji (si ododo). Awon ife-okan ati iro oro si tan yin je titi ase Allahu fi de. Ati pe (Esu) eletan si tan yin je nipa Allahu

[15] Nitori naa, ni oni Awa ko nii gba itanran kan ni owo eyin ati awon t’o sai gbagbo. Ina ni ibugbe yin. Ohun l’o to si yin. Ikangun naa si buru

[16] Se akoko ko ti i to fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki okan won ro fun iranti Allahu ati ohun t’o sokale ninu ododo (iyen, al-Ƙur’an). Ki won si ma se da bi awon ti A fun ni Tira ni isaaju; igba pe lori won, okan won ba le. Opolopo ninu won si ni obileje

[17] E mo pe dajudaju Allahu l’O n so ile di aye leyin ti ile ti ku. A kuku ti salaye awon ayah naa nitori ki e le se laakaye

[18] Dajudaju awon olutore lokunrin ati awon olutore lobinrin, ti won tun ya Allahu ni dukia t’o dara, (Allahu) yoo sadipele re fun won. Esan alapon-onle si wa fun won

[19] Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, awon wonyen ni awon olododo ati elerii ni odo Oluwa won. Esan won ati imole won wa fun won. Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim

[20] E mo pe dajudaju isemi aye yii je ere, iranu, oso, sise iyanran laaarin ara yin ati wiwa opo dukia ati omo. (Iwonyi) da bi ojo (t’o mu irugbin jade). Irugbin re si n jo awon alaigbagbo loju. Leyin naa, o maa gbe. O si maa ri i ni pipon. Leyin naa, o maa di rirun (ti ategun maa fe danu). Iya lile ati aforijin pelu iyonu lati odo Allahu si wa ni orun. Ki si ni isemi aye yii bi ko se igbadun etan

[21] E yara lo sibi aforijin lati odo Oluwa yin ati Ogba Idera ti fife re da bi fife sanmo ati ile. Won pa a lese sile de awon t’o gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. Iyen ni oore ajulo Allahu ti O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla

[22] Adanwo kan ko nii sele ni ori ile tabi (ki o sele) si eyin ayafi ki o ti wa ninu Tira siwaju ki A t’o da eda. Dajudaju iyen rorun fun Allahu

[23] (Isele n to kadara leyin) nitori ki e ma se banuje lori ohun ti o ba bo fun yin ati nitori ki e ma se yo ayoju lori ohun ti O ba fun yin. Allahu ko si nifee si gbogbo onigbeeraga, onifaari

[24] Awon t’o n sahun, ti won si n pa awon eniyan lase ahun sise (ki won mo pe) enikeni ti o ba peyinda (ti ko nawo fun esin), dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Olope

[25] Dajudaju A fi awon eri t’o yanju ran awon Ojise Wa. A so Tira kale fun won ati osuwon nitori ki awon eniyan le ri deede se (laaarin ara won). A tun so irin kale. Ohun ijagun t’o lagbara ati awon anfaani wa ninu re fun awon eniyan nitori ki Allahu le safi han eni t’o n ran (esin) Re ati Ojise Re lowo ni ikoko. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olubori

[26] Dajudaju A fi ise ran (Anabi) Nuh ati (Anabi) ’Ibrohim. A fi ipo Anabi sinu awon aromodomo awon mejeeji pelu Tira (ti A fun won). Olumona wa ninu won. Opolopo ninu won si ni obileje

[27] Leyin naa, A fi awon Ojise Wa tele oripa won. A si mu ‘Isa omo Moryam tele won. A fun un ni al-’Injil. A fi aanu ati ike sinu okan awon t’o tele e. Asa adawa (lai loko tabi lai laya) won se adadaale re ni. A o se e ni oran-anyan le won lori. (Won ko si se adawa fun kini kan) bi ko se lati fi wa iyonu Allahu. Won ko si ri i so bi o se ye ki won so o. Nitori naa, A fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu won ni esan won. Opolopo ninu won si ni obileje

[28] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si gba Ojise Re gbo ni ododo, nitori ki (Allahu) le fun yin ni ilopo meji ninu ike Re ati nitori ki O le fun yin ni imole ti e oo maa fi rin ati nitori ki O le fori jin yin. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[29] (Allahu se bee fun yin) nitori ki awon ahlu-l-kitab le mo pe awon ko ni agbara lori kini kan ninu oore ajulo Allahu. Ati pe dajudaju oore ajulo, owo Allahu l’o wa. O si n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore nla

Obìnrin tí ń bẹ̀bẹ̀

Surah 58

[1] Dajudaju Allahu ti gbo oro (obinrin) t’o n ba o se ariyanjiyan nipa oko re, ti o si n saroye fun Allahu. Allahu si n gbo isorogbesi eyin mejeeji. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Oluriran

[2] Awon t’o n fi eyin iyawo won we ti iya won ninu yin, awon iyawo ki i se iya won. Ko si eni ti o je iya won bi ko se iya ti o bi won lomo. Dajudaju won n so aburu ninu oro ati oro iro. Dajudaju Allahu ni Alamoojukuro, Alaforijin

[3] Awon t’o n fi eyin iyawo won we ti iya won, leyin naa ti won n seri kuro nibi ohun ti won so, won maa tu eru kan sile loko eru siwaju ki awon mejeeji to le sunmo ara won. Iyen ni A n fi se waasi fun yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[4] Eni ti ko ba ri (eru), o maa gba aawe osu meji ni telentele siwaju ki awon mejeeji t’o le sunmo ara won. Eni ti ko ba ni agbara (aawe), o maa bo ogota talika. Iyen nitori ki e le ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojise Re. Iwonyi si ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale fun eda. Iya eleta-elero si wa fun awon alaigbagbo

[5] Dajudaju awon t’o n yapa Allahu ati Ojise Re, A oo yepere won gege bi A se yepere awon t’o siwaju won. A kuku ti so awon ayah t’o yanju kale. Iya ti i yepere eda si wa fun awon alaigbagbo

[6] Ni ojo ti Allahu yoo gbe gbogbo won dide, O si maa fun won ni iro ohun ti won se nise. Allahu se akosile re, awon si gbagbe re. Allahu si ni Arinu-rode gbogbo nnkan

[7] Se o o ri i pe dajudaju Allahu mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile ni? Ko si oro ikoko kan laaarin eni meta afi ki Allahu se ikerin won ati eni marun-un afi ki O se ikefa won. Won kere si iyen, won tun po (ju iyen) afi ki O wa pelu won ni ibikibi ti won ba wa. Leyin naa, O maa fun won ni iro ohun ti won se nise ni Ojo Ajinde. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan. ayah yii ko tumo si pe Paapaa Bibe Allahu wa lori ile aye tabi pe Paapaa Bibe Allahu wa pelu eni kookan. Ti Allahu ba se ikeji eni kan tabi O se iketa eni meji bi ko se pe wiwa Allahu pelu eda Re ni pe “Allahu n gbo ohun eda” ninu surah al-Waƙi‘ah; 56:85 isunmo ti Allahu sunmo eda ju bi a se sunmo ara wa lo duro fun bi awon molaika olugbemi-eda se maa sunmo eni kookan ni akoko ti emi ba fe jade lara eda. Eyi rinle bee ninu ayah 83 ati 84 ninu surah naa. Nitori naa isunmo ti Allahu n toka si ninu awon ayah wonyen ati iru won miiran ko tumo si isokale Allahu wa si inu isan orun eda

[8] Se o o ri awon ti A ko oro ikoko fun, leyin naa ti won tun pada sibi ohun ti A ko fun won. Won n bara won so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. Nigba ti won ba si de odo re, won yoo ki o ni kiki ti Allahu ko fi ki o. Won si n wi sinu emi won pe: "Ki ni ko je ki Allahu je wa niya lori ohun ti a n wi (ni ikoko)!" Ina Jahnamo maa to won. Won maa wo inu re. Ikangun naa si buru

[9] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba n bara yin so oro ikoko, e ma se so oro ikoko lori ese, abosi ati iyapa Ojise. E bara yin so oro ikoko lori ise rere ati iberu Allahu. E beru Allahu, Eni ti won yoo ko yin jo si odo Re

[10] Dajudaju oro ikoko (buruku) n wa lati odo Esu nitori ki o le ko ibanuje ba awon t’o gbagbo ni ododo. Ko si le fi kini kan ko inira ba won afi pelu iyonda Allahu. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

[11] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti won ba so fun yin pe ki e gbara yin laye ninu awon ibujokoo, e gbara yin laye. Allahu yoo f’aye gba yin. Nigba ti won ba so pe: "E dide (sibi ise rere)." E dide (si i). Allahu yoo sagbega awon ipo fun awon t’o gbagbo ni ododo ati awon ti A fun ni imo ninu yin. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[12] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba ba Ojise soro ateso, e fi ore tita siwaju oro ateso yin. Iyen loore julo fun yin. O si fo yin mo julo. Ti e o ba si ri (ore), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[13] Se e n paya (osi) nibi ki e maa ti ore siwaju awon oro ateso yin ni? Nigba ti e o se e, Allahu si gba ironupiwada yin. Nitori naa, e kirun, e yo Zakah. E tele ti Allahu ati Ojise Re. Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[14] Se o o ri awon t’o mu ijo kan ti Allahu binu si ni ore? Won ki i se ara yin, won ko si je ara won. Won yo si maa bura lori iro, won si mo

[15] Allahu ti pese iya lile de won. Dajudaju ohun ti won n se nise buru

[16] Won fi ibura won se aabo; won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Nitori naa, iya ti i yepere eda wa fun won

[17] Awon dukia won ati awon omo won ko nii fi kini kan ro won loro ni odo Allahu. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re

[18] Ni ojo ti Allahu yoo gbe gbogbo won dide patapata, won yo si maa bura fun Un gege bi won se n bura fun yin. Won n lero pe dajudaju awon ti ri nnkan se. Gbo! Dajudaju awon, awon ni opuro

[19] Esu je gaba le won lori. O si mu won gbagbe iranti Allahu. Awon wonyen ni ijo Esu. Gbo! Dajudaju ijo esu, awon ni eni ofo

[20] Dajudaju awon t’o n yapa Allahu ati Ojise Re, awon wonyen wa ninu awon oluyepere julo

[21] Allahu ko o pe: "Dajudaju Mo maa bori; Emi ati awon Ojise Mi." Dajudaju Allahu ni Alagbara, Olubori

[22] O o nii ri ijo kan t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ki won maa nifee awon t’o ba yapa Allahu ati Ojise Re koda ki won je awon baba won, tabi awon omo won tabi awon arakunrin won tabi awon ibatan won. Awon wonyen ni Allahu ti ko igbagbo ododo sinu okan won. Allahu si kun won lowo pelu imole (al-Ƙur’an ati isegun) lati odo Re. O si maa mu won wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). Awon wonyen ni ijo Allahu. Gbo! Dajudaju ijo Allahu, awon ni olujere

Ìlé-kúrò

Surah 59

[1] Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon

[2] Oun ni Eni ti O mu awon t’o sai gbagbo ninu awon ahlu-l-kitab jade kuro ninu ile won fun ikojo akoko. Eyin ko lero pe won yoo jade. Awon naa si lero pe dajudaju awon odi ile won yoo daabo bo awon lodo Allahu. Sugbon Allahu wa ba won ni ibi ti won ko lero; Allahu si ju iberu sinu okan won. Won n fi owo ara won ati owo awon onigbagbo ododo wo awon ile won. Nitori naa, e woye, eyin ti e ni oju iriran

[3] Ati pe ti ko ba je pe Allahu ti ko ijade kuro ninu ilu Modinah le awon ahlu-l-kitab lori ni, dajudaju (Allahu) iba je won niya nile aye. Iya Ina si tun wa fun won ni orun

[4] Iyen nitori pe dajudaju won yapa (ase) Allahu ati Ojise Re. Enikeni ti o ba yapa (ase) Allahu, dajudaju Allahu le nibi iya

[5] Eyin ko nii ge igi dabinu kan tabi ki e fi sile ki o duro sori gbongbo re, (afi) pelu iyonda Allahu. (O ri bee) nitori ki O le doju ti awon obileje ni

[6] Ohunkohun ti Allahu ba da pada lati odo won fun Ojise Re, ti e o gbe esin ati rakunmi sare fun (ti Ojise Re ni). Sugbon Allahu yoo maa fun awon Ojise Re ni agbara lori eni ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[7] Ohunkohun ti Allahu ba da pada lati odo awon ara ilu fun Ojise Re, (o je) ti Allahu ati ti Ojise ati ti awon ibatan, awon omo orukan, awon talika ati onirin-ajo ti agara da nitori ki o ma baa je adapin laaarin awon oloro ninu yin. Ohunkohun ti Ojise ba fun yin, e gba a. Ohunkohun ti o ba si ko fun yin, e jawo ninu re. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu le nibi iya

[8] (Ikogun naa tun wa fun) awon alaini, (iyen,) al-Muhajirun, awon ti won le jade kuro ninu ile won ati nibi dukia won, ti won si n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Allahu, ti won si n saranse fun (esin) Allahu ati Ojise Re. Awon wonyen ni awon olododo

[9] Awon t’o n gbe ninu ilu Modinah, ti won si ni igbagbo ododo siwaju won, won nifee awon t’o fi ilu Mokkah sile wa si odo won (ni ilu Modinah). Won ko si ni bukata kan ninu igba-aya won si nnkan ti won fun won. Won si n gbe ajulo fun won lori emi ara won, koda ki o je pe awon gan-an ni bukata (si ohun ti won fun won). Enikeni ti A ba so nibi ahun ati okanjua inu emi re, awon wonyen, awon ni olujere

[10] Awon t’o de leyin won n so pe: "Oluwa wa, forijin awa ati awon omo iya wa t’o siwaju wa ninu igbagbo ododo. Ma se je ki inunibini wa ninu okan wa si awon t’o gbagbo ni ododo. Oluwa wa, dajudaju Iwo ni Alaaanu, Asake-orun

[11] Se o o ri awon t’o sobe-selu ti won n wi fun awon omo iya won, awon t’o sai gbagbo ninu awon ahlul-kitab, pe "Dajudaju ti won ba le yin jade (kuro ninu ilu), awa naa gbodo jade pelu yin ni. Awa ko si nii tele ase eni kan lori yin laelae. Ti won ba si gbe ogun dide si yin, awa gbodo se iranlowo fun yin ni." Allahu si n jerii pe dajudaju opuro ni won

[12] Dajudaju ti won ba le won jade, won ko nii jade pelu won. Dajudaju ti won ba si gbogun ti won, won ko nii se iranlowo fun won. Ti won ba si wa iranlowo won, dajudaju won yoo peyin da (lati fese fee). Leyin naa, won ko si nii ran won lowo

[13] Dajudaju eyin ni erujeje t’o lagbara ju Allahu lo ninu igba-aya won. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko gbo agboye

[14] Won ko le parapo doju ija ko yin afi (ki won) wa ninu odi ilu tabi (ki won wa) leyin awon ogiri. Ogun aarin ara won gan-an le. O n lero pe won wa ni irepo ni, otooto si ni okan won wa. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko ni laakaye

[15] Apeere won da bi awon t’o siwaju won ti ko ti i pe lo titi. Won to aburu oro ara won wo. Iya eleta-elero si wa fun won

[16] Apeere won da bi Esu nigba ti o ba wi fun eniyan pe: "Sai gbagbo." Nigba ti o ba sai gbagbo (tan), o maa wi pe: "Dajudaju emi yowo-yose kuro ninu oro re. Dajudaju emi n paya Allahu, Oluwa gbogbo eda

[17] Nitori naa, ikangun awon mejeeji ni pe, dajudaju awon mejeeji yoo wa ninu Ina. Olusegbere ni awon mejeeji ninu re. Iyen si ni esan awon alabosi

[18] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu. Ki emi kan si woye si ohun ti o ti siwaju fun ola (alukiyaamo). E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

[19] Ki e si ma se da bi awon t’o gbagbe Allahu. (Allahu) si mu won gbagbe emi ara won. Awon wonyen, awon ni obileje

[20] Awon ero inu Ina ati awon ero inu Ogba Idera ko dogba. Awon ero inu Ogba Idera, awon ni olujere

[21] Ti o ba je pe A so al-Ƙur’an yii kale sori apata ni, dajudaju o maa ri i ti o maa wale, ti o maa fo petepete fun ipaya Allahu. Iwonyi ni awon apeere ti A n fi lele fun awon eniyan nitori ki won le ronu jinle

[22] Oun ni Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Onimo ikoko ati gbangba. Oun ni Ajoke-aye, Asake-orun

[23] Oun ni Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Oba (eda), Eni-mimo julo, Alailabuku, Olujerii-Ojise-Re, Olujerii-eda Alagbara, Olujeni-nipa, Atobi. Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won fi n sebo si I

[24] Oun ni Allahu, Eledaa, Olupile-eda, Oluyaworan-eda. TiRe ni awon oruko t’o dara julo. Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile n safomo fun Un. Oun si ni Alagbara, Ologbon

Obìnrin tí a gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò

Surah 60

[1] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu ota Mi ati ota yin ni ore ti e oo maa fi ife han si. Won kuku ti sai gbagbo ninu ohun ti o de ba yin ninu ododo. Won yo Ojise ati eyin naa kuro ninu ilu nitori pe, e gbagbo ninu Allahu, Oluwa yin. Ti eyin ba jade fun ogun nitori esin Mi ati nitori wiwa iyonu Mi, (se) eyin yoo tun maa ni ife koro si won ni! Emi si nimo julo nipa ohun ti e fi pamo ati ohun ti e fi han. Enikeni ti o ba se bee ninu yin, dajudaju o ti sina kuro loju ona taara

[2] Ti owo won ba ba yin, won maa di ota fun yin. Won yo si fi owo won ati ahon won nawo aburu si yin. Won si maa fe ki o je pe e di alaigbagbo

[3] Awon ebi yin ati awon omo yin ko le se yin ni anfaani; ni Ojo Ajinde ni Allahu maa sepinya laaarin yin. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

[4] Dajudaju awokose rere ti wa fun yin ni ara (Anabi) ’Ibrohim ati awon t’o wa pelu re. Nigba ti won so fun ijo won pe: "Dajudaju awa yowo-yose kuro ninu oro yin ati ohun ti e n josin fun leyin Allahu. A tako yin. Ota ati ikorira si ti han laaarin wa titi laelae ayafi igba ti e ba to gbagbo ninu Allahu nikan soso. - Afi oro ti (Anabi) ’Ibrohim so fun baba re pe: "Dajudaju mo maa toro aforijin fun o, emi ko si ni ikapa kini kan fun o lodo Allahu. - Oluwa wa, Iwo l’a gbarale. Odo Re l’a seri pada si (nipa ironupiwada). Odo Re si ni abo eda

[5] Oluwa wa, ma se wa ni adanwo fun awon t’o sai gbagbo. Forijin wa, Oluwa wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara, Ologbon

[6] Dajudaju awokose rere ti wa fun yin ni ara won fun eni t’o n reti (esan) Allahu ati Ojo Ikeyin. Enikeni ti o ba peyin da, dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Eleyin

[7] O le je pe Allahu yoo fi ife si aarin eyin ati awon ti e mu ni ota ninu won (iyen, nigba ti won ba di musulumi). Allahu ni Alagbara. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[8] Allahu ko ko fun yin nipa awon ti ko gbe ogun ti yin nipa esin, ti won ko si le yin jade kuro ninu ilu yin, pe ki e se daadaa si won, ki e si se deede si won. Dajudaju Allahu feran awon oluse-deede

[9] Ohun ti Allahu ko fun yin nipa awon t’o gbogun ti yin ninu esin, ti won si le yin jade kuro ninu ilu yin, ti won tun se iranlowo (fun awon ota yin) lati le yin jade, ni pe (O ko fun yin) lati mu won ni ore. Enikeni ti o ba mu won ni ore, awon wonyen, awon ni alabosi

[10] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin ba wa ba yin, ti won gbe ilu awon alaigbagbo ju sile fun aabo esin won, e bi won ni ibeere. Allahu nimo julo nipa igbagbo won. Nitori naa, ti e ba mo won si onigbagbo ododo, e ma se da won pada si odo awon alaigbagbo. Awon onigbagbo ododo lobinrin ko letoo si won. Awon alaigbagbo lokunrin ko si letoo si won. E fun (awon alaigbagbo lokunrin) ni owo ti won na (ni owo-ori obinrin naa). Ko si si ese fun eyin naa pe ki e fe won nigba ti e ba ti fun (awon obinrin wonyi) ni owo-ori won. E ma se fi owo-ori awon obinrin yin ti won je alaigbagbo mu won mole (gege bi iyawo yin lai je pe won gba ’Islam pelu yin). E beere ohun ti e na (ni owo-ori won lowo alaigbagbo lokunrin ti won sa lo ba). Ki awon (alaigbagbo lokunrin naa) beere ohun ti awon naa na (ni owo-ori won lowo eyin ti onigbagbo ododo lobinrin sa wa ba). Iyen ni idajo Allahu. O si n dajo laaarin yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon

[11] Ti kini kan lati odo awon iyawo yin ba bo mo yin lowo si odo awon alaigbagbo, ti e si kore ogun, e fun awon ti iyawo won sa lo ni iru odiwon ohun ti won na (ni owo-ori). Ki e si beru Allahu, Eni ti eyin ni igbagbo ododo ninu Re

[12] Iwo Anabi, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin ba wa ba o, ti won n se adehun fun o pe awon ko nii fi kini kan sebo si Allahu, awon ko nii jale, awon ko nii se sina, awon ko nii pa omo won, awon ko nii mu adapa iro wa, adapa iro ti won n mu wa laaarin owo won ati ese won (iyen ni gbigbe oyun oloyun fun oko won), awon ko si nii yapa re nibi nnkan daadaa, nigba naa ba won se adehun, ki o si ba won toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[13] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu ijo kan ti Allahu ti binu si ni ore. Dajudaju won ti soreti nu nipa orun, gege bi awon alaigbagbo t’o wa ninu saree (se soreti nu nipa ike)

Àwọn Safu

Surah 61

[1] Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon

[2] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nitori ki ni e se n so ohun ti e o nii se nise

[3] O je ohun ibinu t’o tobi ni odo Allahu pe ki e so ohun ti e o nii se

[4] Dajudaju Allahu feran awon t’o n jagun fun esin Re (ti won to ni) owoowo bi eni pe ogiri ile ti won le po mora won ni won

[5] (Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "Eyin ijo mi, nitori ki ni e oo se fi inira kan mi. E si kuku mo pe dajudaju Ojise Allahu ni emi je si yin." Nigba ti won si ye (kuro nibi ododo), Allahu ye okan won. Allahu ko si nii fi ona mo ijo obileje

[6] (Ranti) nigba ti ‘Isa omo Moryam so pe: "Eyin omo ’Isro’il, dajudaju emi ni Ojise Allahu si yin. Mo n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju mi ninu Taorah. Mo si n mu iro-idunnu wa nipa Ojise kan t’o n bo leyin mi. Oruko re ni ’Ahmod." Nigba ti o ba si wa ba won pelu awon eri t’o yanju, won a wi pe: "Idan ponnbele ni eyi

[7] Ta si ni o sabosi t’o tayo eni ti o da adapa iro mo Allahu, ti won si n pe e sinu ’Islam! Allahu ko si nii fi ona mo ijo alabosi

[8] Won n gbero lati fi (oro) enu won pa imole Allahu. Allahu yo si mu imole Re tan kari, awon alaigbagbo ibaa korira re

[9] (Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re

[10] Eyin ti e gbagbo ni ododo, se ki Ng toka yin si okowo kan ti o maa gba yin la ninu iya eleta-elero

[11] E gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, e jagun soju ona (esin) Allahu pelu awon dukia yin ati emi yin. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo

[12] (Allahu) maa fori ese yin jin yin. O si maa mu yin wo inu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re ati awon ibugbe t’o dara ninu awon Ogba Idera gbere. Iyen ni erenje nla

[13] Ati nnkan miiran ti e tun nifee si; (iyen,) aranse lati odo Allahu ati isegun t’o sunmo. Ki o si fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu

[14] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je alaranse fun esin Allahu gege bi (Anabi) ‘Isa omo Moryam se so fun awon omoleyin re pe: "Ta ni o maa se iranlowo fun mi nipa esin Allahu?" Awon omoleyin re so pe: "Awa ni alaranse fun esin Allahu." Igun kan ninu awon omo ’Isro’il gba a gbo ni ododo nigba naa, igun kan si sai gbagbo ninu re. A si fun awon t’o gbagbo lagbara lori awon ota won; won si di olubori

Ọjọ́ Ìsinmi

Surah 62

[1] Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun to wa ninu ile n se afomo fun Allahu, Oba eda, Eni-Mimo julo, Alagbara, Ologbon

[2] Oun ni Eni ti O gbe dide laaarin awon alaimoonkomoonka (alainitira) Ojise kan lara won. O n ke awon ayah Re fun won. O n fo won mo (ninu ese). O si n ko won ni Tira ati ogbon ijinle (iyen, sunnah), bi o tile je pe teletele won ti wa ninu isina ponnbele

[3] (Ise jije re tun wa fun) awon miiran ti won maa wa ninu awon (omoleyin re), amo ti won ko ti i rin kan won. (Allahu) Oun ni Alagbara, Ologbon

[4] Iyen ni oore ajulo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore-ajulo nla

[5] Apejuwe ijo ti A fun ni Taorah, leyin naa ti won ko tele e, o da bi apejuwe ketekete ti o ru eru awon tira. Aburu ni apejuwe awon t’o pe awon ayah Allahu niro. Allahu ko si nii fi ona mo ijo alabosi

[6] So pe: "Eyin yehudi, ti e ba lero pe dajudaju eyin ni ore Allahu dipo awon eniyan (yooku), e toro iku nigba naa ti e ba je olododo

[7] Won ko nii toro re laelae nitori ohun ti owo won ti ti siwaju. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi

[8] So pe: "Dajudaju iku ti e n sa fun, dajudaju o maa pade yin. Leyin naa, won yoo da yin pada si odo Onimo-ikoko ati gbangba. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

[9] Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti won ba pe irun ni ojo Jum‘ah, e yara lo sibi iranti Allahu, ki e si pa kata-kara ti. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo

[10] Nigba ti won ba si pari irun, e tuka si ori ile, ki e si maa wa ninu oore Allahu. E ranti Allahu ni opolopo nitori ki e le jere

[11] Nigba ti won ba ri oja kan tabi iranu kan, won yoo da lo sibe. Won yo si fi o sile lori iduro. So pe: "Nnkan ti o wa ni odo Allahu l’oore ju iranu ati oja lo. Allahu si l’oore julo ninu awon olupese

Àwọn Alágàbàgebè

Surah 63

[1] Nigba ti awon sobe-selu musulumi ba wa si odo re, won a wi pe: “A n jerii pe dajudaju iwo, Ojise Allahu ni o.” Allahu si mo pe dajudaju iwo, Ojise Re ni o. Allahu si n jerii pe dajudaju awon sobe-selu musulumi, opuro ni won

[2] Won fi awon ibura won se aabo (fun emi ara won), won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu; dajudaju ohun ti won n se nise buru

[3] (Won se) iyen nitori pe won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo. Nitori naa, A ti fi edidi di okan won; won ko si nii gbo agboye

[4] Nigba ti o ba ri won, irisi won yoo jo o loju. Ti won ba n soro, iwo yoo teti gbo oro won. Won si da bi igi ti won gbe ti ogiri. Won si n lero pe gbogbo igbe (ibosi) n be lori won (nipa isobe-selu won). Ota ni won. Nitori naa, sora fun won. Allahu ti sebi le won. Bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo

[5] Ati pe nigba ti won ba so fun won pe: “E wa ki Ojise ba yin toro aforijin.” Won a gbunri. O si maa ri won ti won yoo maa gbunri lo, ti won yoo maa segberaga

[6] Bakan naa ni fun won; yala o ba won toro aforijin tabi o o ba won toro aforijin. Allahu ko nii forijin won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje

[7] Awon ni awon t’o n wi pe: “Eyin ko gbodo na owo fun awon t’o wa lodo Ojise Allahu titi won yoo fi fonka. Ti Allahu si ni awon apoti-oro sanmo ati ile, sugbon awon sobe-selu musulumi ko nii gbo agboye

[8] Won n wi pe: “Dajudaju ti a ba pada de sinu ilu Modinah, nse ni awon alagbara (ilu) yoo yo awon eni yepere jade kuro ninu ilu." Agbara si n je ti Allahu, ati ti Ojise Re ati awon onigbagbo ododo, sugbon awon sobe-selu musulumi ko mo

[9] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se je ki awon dukia yin ati awon omo yin ko airoju ba yin nibi iranti Allahu. Enikeni ti o ba ko sinu (airoju) yen, awon wonyen, awon ni eni ofo

[10] E na ninu ohun ti A pese fun yin siwaju ki iku to de ba eni kan yin, ki o wa wi pe: "Oluwa mi, ki o si je pe O lo mi lara si i titi di igba kan to sunmo, emi iba si le maa tore, emi iba si wa lara awon eni rere

[11] Allahu ko si nii lo emi kan lara nigba ti ojo iku re ba de. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

Ìjákulẹ̀

Surah 64

[1] Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n se afomo fun Allahu. TiRe ni ijoba. TiRe si ni ope. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[2] Oun ni Eni ti O seda yin. Alaigbagbo wa ninu yin. Onigbagbo ododo si wa ninu yin. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se

[3] O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O ya aworan yin. O si se awon aworan yin daradara. Odo Re si ni abo eda

[4] O mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. O si mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n safi han re. Allahu si ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda

[5] Se iro awon t’o sai gbagbo ni isaaju ko ti i de ba yin ni? Nitori naa, won to iya oran won wo. Iya eleta-elero si wa fun won

[6] Iyen nitori pe dajudaju awon Ojise won n wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Won si wi pe: "Se abara l’o maa fi ona mo wa?" Nitori naa, won sai gbagbo. Won si peyin da (si ododo). Allahu si roro lai si awon. Ati pe Allahu ni Oloro, Olope

[7] Awon t’o sai gbagbo lero pe A o nii gbe won dide. So pe: "Bee ko, mo fi Oluwa mi bura, dajudaju Won yoo gbe yin dide. Leyin naa, Won yoo fun yin ni iro ohun ti e se nise. Iyen si je irorun fun Allahu

[8] Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re ati imole ti A sokale. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se

[9] Ni ojo ti (Allahu) yoo ko yin jo fun ojo akojo. Iyen ni ojo ere ati adanu. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo ni ododo, ti o si se ise rere, (Allahu) yoo pa awon asise re re fun un. O si maa mu un wo inu Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen si ni erenje nla

[10] Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re. Ikangun naa si buru

[11] Adanwo kan ko le sele ayafi pelu iyonda Allahu. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo, Allahu maa fi okan re mona. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan

[12] Ki e tele ti Allahu. Ki e si tele ti Ojise. Ti e ba gbunri, ise-jije ponnbele lojuse Ojise Wa

[13] Allahu, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale

[14] Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju ota wa fun yin ninu awon iyawo yin ati awon omo yin. Nitori naa, e sora fun won. Ti e ba samojukuro, ti e safojufo, ti e si saforijin (fun won), dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

[15] Ifooro ni awon dukia yin ati awon omo yin. Allahu si ni esan nla wa ni odo Re

[16] Nitori naa, e beru Allahu bi e ba se lagbara mo. E gbo oro (Allahu), e tele e, ki e si nawo (fun esin Re) loore julo fun emi yin. Enikeni ti A ba so nibi ahun ati okanjua inu emi re, awon wonyen, awon ni olujere

[17] Ti e ba ya Allahu ni dukia t’o dara, O maa sadipele re fun yin. O si maa forijin yin. Allahu si ni Olumoore, Alafarada

[18] Onimo-ikoko ati gbangba, Alagbara, Ologbon

Ìkọ̀sílẹ̀

Surah 65

[1] Iwo Anabi, nigba ti e ba fe ko awon obinrin sile, e ko won sile pelu sise onka ojo opo fun ikosile won. Ki e si so onka ojo opo. Ki e beru Allahu, Oluwa yin. E ma se mu won jade kuro ninu ile won, awon naa ko si gbodo jade afi ti won ba lo se ibaje t’o foju han. Iwonyen si ni awon enu-ala ti Allahu gbekale. Enikeni ti o ba tayo awon enu-ala ti Allahu gbekale, o kuku ti sabosi si emi ara re. Iwo ko si mo boya Allahu maa mu oro titun sele leyin iyen

[2] Nigba ti won ba fe pari onka ojo opo won, e mu won modo ni ona t’o dara tabi ki e ko won sile ni ona t’o dara. E fi awon onideede meji ninu yin jerii si i. Ki e si gbe ijerii naa duro ni titori ti Allahu. Iyen ni A n fi se waasi fun enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa fun un ni ona abayo (ninu isoro)

[3] O si maa pese fun un ni aye ti ko ti rokan. Ati pe enikeni ti o ba gbekele Allahu, O maa to o. Dajudaju Allahu yoo mu oro Re de opin. Dajudaju Allahu ti ko odiwon akoko fun gbogbo nnkan

[4] Awon obinrin t’o ti soreti nu nipa nnkan osu sise ninu awon obinrin yin, ti e ba seyemeji, onka ojo ikosile won ni osu meta. (Bee naa ni fun) awon ti ko ti i maa se nnkan osu. Awon oloyun, ipari onka ojo opo ikosile tiwon ni pe ki won bi oyun inu won. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa se oro re ni irorun

[5] Iyen ni ase Allahu, ti O sokale fun yin. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa pa awon asise re re. O si maa je ki esan re tobi

[6] E fun won ni ibugbe ninu ibugbe yin bi aye se gba yin mo. E ma se ni won lara lati ko ifunpinpin ba won. Ti won ba je oloyun, e nawo le won lori titi won yoo fi bi oyun inu won. Ti won ba n fun omo yin ni oyan mu, e fun won ni owo-oya won. E damoran laaarin ara yin ni ona t’o dara. Ti oro ko ba si rogbo laaarin ara yin, ki elomiiran ba oko (fun omo) ni oyan mu

[7] Ki oloro na ninu oro re. Eni ti A si diwon arisiki re fun (niwonba), ki o na ninu ohun ti Allahu fun un. Allahu ko labo emi kan lorun ayafi nnkan ti O fun un. Allahu yo si mu irorun wa leyin inira

[8] Meloo meloo ninu awon ilu ti won yapa ase Oluwa Re ati awon Ojise Re. A si maa siro ise won ni isiro lile. Ati pe A maa je won niya t’o buru gan-an

[9] Nitori naa, won to iya oran won wo. Ikangun oro won si je ofo

[10] Allahu ti pese iya lile sile de won. Nitori naa, e beru Allahu, eyin onilaakaye ti e gbagbo ni ododo. Allahu kuku ti so iranti kale fun yin

[11] Ojise kan ti o maa ke awon ayah Allahu t’o yanju fun yin nitori ki o le mu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won tun se awon ise rere, kuro ninu awon okunkun lo sinu imole. Enikeni ti o ba gba Allahu gbo ni ododo, ti o si n se ise rere, O maa mu un wo inu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Dajudaju Allahu ti se arisiki t’o dara julo fun un

[12] Allahu ni Eni ti O seda awon sanmo meje ati ile ni (onka) iru re. Ase n sokale laaarin won nitori ki e le mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan. Ati pe dajudaju Allahu fi imo rogba yi gbogbo nnkan ka

Ìfòfindè

Surah 66

[1] Iwo Anabi, nitori ki ni o se maa so nnkan ti Allahu se ni eto fun o di eewo? Iwo n wa iyonu awon iyawo re. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun

[2] Dajudaju Allahu ti se alaye ofin itanran ibura yin fun yin. Allahu ni Oluranlowo yin. Oun si ni Onimo, Ologbon

[3] Ranti nigba ti Anabi ba okan ninu awon iyawo re s’oro asiri. Nigba ti (eni t’o ba soro, iyen Hafsoh) si soro naa fun (‘A’isah), Allahu si fi han Anabi (pe elomiiran ti gbo si i). Anabi si so apa kan re (fun Hafsoh pe: "O ti fi oro Moriyah to ‘A’isah leti."). O si fi apa kan sile (iyen, oro nipa ipo arole). Amo nigba ti (Anabi) fi iro naa to o leti, Hafsoh) so pe: "Ta ni o fun o ni iro eyi?" (Anabi) so pe: "Onimo, Alamotan l’O fun mi ni iro naa

[4] Ti eyin mejeeji ba ronu piwada si odo Allahu, (O maa gba ironupiwada yin). Sebi okan yin kuku ti te (sibi ki Anabi ma fee Moriyah). Ti e ba si ran ara yin lowo (lati ko ibanuje) ba a, dajudaju Allahu ni Oluranlowo re, ati (molaika) Jibril ati eni rere ninu awon onigbagbo ododo. Leyin iyen, awon molaika ti won je oluranlowo (tun wa fun un)

[5] O see se, ti o ba ko yin sile, ki Oluwa re fi awon obinrin kan, ti won loore ju yin lo ropo fun un, (ti won maa je) musulumi, onigbagbo ododo, awon olutele-ase, awon oluronupiwada, olujosin, olugbaawe ni adelebo ati wundia

[6] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e so emi ara yin ati awon ara ile yin nibi Ina. Eniyan ati okuta ni nnkan ikona re. Awon molaika t’o roro, ti won le ni eso re. Won ko nii yapa ase Allahu nibi ohun ti O ba pa lase fun won. Won si n se ohun ti won ba pa lase fun won

[7] Eyin ti e sai gbagbo, e ma se saroye ni ojo oni. Ohun ti e n se nise ni A oo fi san yin ni esan

[8] Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ronu piwada si odo Allahu ni ironupiwada ododo. O see se pe Oluwa yin maa pa awon asise yin re fun yin. O si maa mu yin wo inu awon Ogba Idera ti awon odo n san ni isale re. Ni ojo ti Allahu ko nii doju ti Anabi ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re. Imole won yoo maa tan ni iwaju won ati ni owo otun won. Won yoo so pe: "Oluwa wa, pe imole wa fun wa, ki O si forijin wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[9] Iwo Anabi, gbogun ti awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Ki o si le mo won. Ibugbe won si ni ina Jahanamo. Ikangun naa si buru

[10] Allahu fi iyawo (Anabi) Nuh ati iyawo (Anabi) Lut se apeere fun awon t’o sai gbagbo. Awon mejeeji wa labe erusin meji rere ninu awon erusin Wa. Awon (obinrin) mejeeji si janba awon oko won. Awon oko won ko si fi kini kan ro won loro lodo Allahu. A o si so fun awon obinrin mejeeji pe: "E wo inu Ina pelu awon oluwole (sinu Ina)

[11] Allahu tun fi iyawo Fir‘aon se apeere fun awon t’o gbagbo. Nigba ti o so pe: "Oluwa mi, ko ile kan fun mi lodo Re ninu Ogba Idera. La mi lowo Fir‘aon ati ise owo re. Ki O si la mi lowo ijo alabosi

[12] Ati Moryam omobinrin ‘Imron, eyi ti o so abe re. A si fe ategun si i lara ninu ategun emi ti A da. O gbagbo lododo ninu awon oro Oluwa re ati awon Tira Re. O si wa ninu awon olutele-ase Allahu

Àkóso

Surah 67

[1] Ibukun ni fun Eni ti ijoba wa ni Owo Re. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan

[2] Eni ti O da iku ati isemi nitori ki o le dan yin wo; ewo ninu yin l’o maa se ise rere julo. Oun si ni Alagbara, Alaforijin

[3] Eni ti O da awon sanmo meje ni ipele ipele. O o le ri aigunrege kan lara eda Ajoke-aye. Nitori naa, wo o pada, nje o ri oju sisan kan (lara sanmo)

[4] Leyin naa, wo o pada ni ee meji, ki oju re pada si odo re pelu iyepere. O si maa kaaare

[5] Dajudaju A ti fi (awon irawo t’o n tanmole bi) atupa se sanmo ile aye ni oso. A tun se won ni eta-irawo ti won n ju mo awon esu. A si pese iya Ina t’o n jo fofo sile de won

[6] Iya ina Jahanamo si wa fun awon t’o sai gbagbo. Ikangun naa si buru

[7] Nigba ti won ba ju won sinu re, won yoo maa gbo kikun re, ti o si maa ru soke

[8] Ina maa fee pinra re lati ara ibinu. Igbakigba ti won ba ju ijo kan sinu re, awon eso Ina yoo maa bi won leere pe: "Nje olukilo kan ko wa ba yin bi

[9] Won yoo wi pe: "Rara, dajudaju olukilo kan ti wa ba wa, sugbon a pe e ni opuro. A si wi pe Allahu ko so nnkan kan kale. Ki ni eyin bi ko se pe e wa ninu isina t’o tobi

[10] Won tun wi pe: "Ti o ba je pe a gboran ni tabi pe a se laakaye ni, awa ko nii wa ninu ero inu Ina jijo

[11] Won si jewo ese won. Nitori naa, ijinna si ike Allahu yo wa fun awon ero inu Ina t’o n jo fofo

[12] Dajudaju awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko, aforijin ati esan t’o tobi n be fun won

[13] E wi oro yin ni jeeje tabi e wi i soke, dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu awon igba-aya eda

[14] Se (Allahu) ko mo eni t’O da ni? Oun si ni Alaaanu, Alamotan

[15] Oun ni Eni ti O ro ile fun yin. Nitori naa, e rin ni awon agbegbe re kaakiri, ki e si je ninu arisiki Re. Odo Re si ni ajinde eda wa

[16] Se e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le je ki ile gbe yin mi? Nigba naa, ile yo si maa mi titi

[17] Tabi e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le fi okuta ina ranse si yin ni? Nigba naa, e si maa mo bi ikilo Mi ti ri

[18] Awon t’o siwaju won kuku pe ododo niro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri

[19] Se won ko ri awon eye ti o wa ni oke won, ti (won) n na iye apa (won), ti won si n pa a mora? Kini kan ko mu won duro (sinu ofurufu) afi Ajoke-aye. Dajudaju Oun si ni Oluriran nipa gbogbo nnkan

[20] Ta ni eni ti o maa je omo ogun fun yin, ti o maa ran yin lowo leyin Ajoke-aye? (Ninu) ki ni awon alaigbagbo wa bi ko se ninu etan

[21] Ta ni eni ti o maa pese fun yin ti O ba da arisiki Re duro? Nse ni won n sori kunkun si i ninu igberaga ati sisa fun ododo

[22] Nje eni t’o n rin ni idojubole l’o mona julo ni tabi eni t’o n rin san an loju ona taara

[23] So pe: "Oun ni Eni ti O seda yin. O si se igboro, iriran ati awon okan fun yin. Ope ti e n da si kere pupo

[24] So pe: "Oun ni Eni ti O da yin si ori ile. Odo Re si ni won yoo ko yin jo si

[25] Won n wi pe: "Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo

[26] So pe: "Odo Allahu nikan ni imo (nipa) re wa. Emi kan je olukilo ponnbele ni

[27] Nigba ti won ba ri i t’o sunmo, oju awon t’o sai gbagbo yoo koro wa fun ibanuje. A o si so fun won pe: "Eyi ni ohun ti e n pe

[28] So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba pa emi ati awon t’o wa pelu mi re, tabi ti O ba ke wa (se e le di I lowo ni?) Nitori naa, ta ni o maa gba awon alaigbagbo la ninu iya eleta-elero

[29] So pe: "Oun ni Ajoke-aye. Awa gba A gbo. Oun si la gbarale. Laipe e maa mo ta ni o wa ninu isina ponnbele

[30] So pe: " E so fun mi, ti omi yin ba gbe wa, ta ni eni ti o maa mu omi iseleru wa ba yin

Kàlámù

Surah 68

[1] Nun. (Allahu bura pelu) gege ikowe ati ohun ti awon molaika n ko sile

[2] Iwo ki i se were nipa idera Oluwa re

[3] Ati pe dajudaju esan ti ko nii dawo duro ti wa fun o

[4] Dajudaju iwo si wa lori iwa aponle

[5] Laipe iwo yoo ri i, awon naa yo si ri i

[6] ewo ninu yin ni were

[7] Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa awon olumona

[8] Nitori naa, ma se tele awon olupe-ododo-niro

[9] Ati pe won fe ki o dewo, ki awon naa si dewo

[10] Ma se tele gbogbo eni ti ibura re po, eni yepere

[11] abuni, alarinka t’o n sofofo kiri

[12] oludena ise rere, alakoyo, elese

[13] odaju. Leyin iyen, asawo ni

[14] Nitori pe o ni dukia ati awon omokunrin

[15] nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa wi pe: “Akosile alo awon eni akoko (niwonyi)”

[16] A maa fi ami si i ni gongori imu

[17] Dajudaju Awa dan won wo gege bi A se dan awon ologba wo nigba ti won bura pe dajudaju awon yoo ka gbogbo eso ogba naa ni owuro kutukutu

[18] Won ko si se ayafi pe "ti Allahu ba fe

[19] Adanwo t’o n yi nnkan po lati odo Oluwa re si yi ogba naa po, nigba ti won sun lo

[20] O si da bi oko agedanu (ti won ti resun)

[21] Won n pera won ni owuro kutukutu

[22] pe e ji lo si oko yin ti e ba fe ka eso

[23] Won lo, won si n fi ohun jeeje bara won soro

[24] pe ni oni mekunnu kan ko gbodo wonu re wa ba yin

[25] Won ji lo lori ero-okan kan (pe) awon lagbara

[26] Nigba ti won ri i, won wi pe: "Dajudaju awa ti sina

[27] Rara o, won se ikore oko leewo fun wa ni

[28] Eni t’o duro deede julo ninu won so pe: "Se emi ko so fun yin pe eyin ko se safomo fun Allahu (pe "a maa kore oko wa, ’in sa ’Allahu)

[29] Won wi pe: "Mimo ni fun Oluwa wa, dajudaju awa je alabosi

[30] Apa kan won koju si apa kan; won si n dara won lebi

[31] Won wi pe: "Egbe wa o! Dajudaju awa je olutayo-enu ala

[32] O see se ki Oluwa wa fi eyi t’o dara ju eyi lo paaro re fun wa. Dajudaju odo Oluwa wa ni awa n rokan oore si

[33] Bayen ni iya naa se ri (fun won). Iya orun si tobi julo, ti o ba je pe won mo

[34] Dajudaju awon Ogba Idera wa fun awon oluberu lodo Oluwa won

[35] Se A maa se awon musulumi bi (A se maa se) awon elese bi

[36] Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii na

[37] Tabi tira kan wa fun yin ti e n kekoo ninu re

[38] pe dajudaju eyin le ni ohun ti e ba n sa lesa ninu idajo

[39] Nje e ni awon adehun kan lodo wa ti o maa wa titi di Ojo Ajinde pe: "Dajudaju tiyin ni idajo ti e ba ti mu wa

[40] Bi won leere wo pe ewo ninu won l’o le fowo iyen soya

[41] Tabi won ni awon orisa kan? Ki won mu awon orisa won wa nigba naa ti won ba je olododo

[42] Ni ojo ti A maa si ojugun sile, A si maa pe won sibi iforikanle, won ko si nii le se e

[43] Oju won yoo wale. Iyepere maa bo won mole. Won kuku ti pe won sibi iforikanle nigba ti won ni alaafia (won ko si kirun)

[44] Nitori naa, fi Emi ati eni t’o n pe oro yii niro sile. A oo maa de won leke lati je won niya ni aye ti won ko mo

[45] Mo n lora fun won ni. Dajudaju ete Mi lagbara

[46] Tabi o n beere owo-oya kan lodo won, ni gbese fi wo won lorun

[47] Tabi lodo won ni (walaa) ikoko wa ni won ba n ko o (sita)

[48] Nitori naa, se suuru fun idajo Oluwa re. Ki iwo ma si se da bi eleja (iyen, Anabi Yunus) nigba ti o pe (Allahu) pelu ibanuje

[49] Ti ko ba je pe ike kan lati odo Oluwa re le e ba, won iba ju u sori ile gbansasa (lati inu eja) ni eni-eebu

[50] Nitori naa, Oluwa re sa a lesa. O si se e ni ara awon eni rere

[51] Awon t’o sai gbagbo fee fi oju won gbe o subu nigba ti won gbo iranti naa. Won si n wi pe: "Dajudaju were ma ni

[52] Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda

Òtítọ́

Surah 69

[1] Isele Ododo

[2] Ki ni Isele Ododo

[3] Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Isele Ododo

[4] Awon ijo Thamud ati ijo ‘Ad pe Ipaya niro

[5] Ni ti ijo Thamud, won fi igbe t’o tayo enu-ala pa won re

[6] Ni ti ijo ‘Ad, won fi ategun lile t’o tayo enu-ala pa won re

[7] O de e si won fun oru meje ati osan mejo lai dawo duro. O si maa ri ijo naa ti won ti ku sinu re bi eni pe kukute igi dabinu t’o ti luho ninu ni won

[8] Nje o ri eni kan ninu won t’o se ku bi

[9] Fir‘aon ati awon t’o siwaju re ati awon ilu ti won doju re bole de pelu awon asise

[10] Won yapa Ojise Oluwa won. O si gba won mu ni igbamu alekun

[11] Dajudaju nigba ti omi tayo enu-ala. A gbe yin gun oko oju-omi

[12] Nitori ki A le fi se iranti fun yin ati nitori ki eti t’o n so nnkan le so o

[13] Nigba ti won ba fon fere oniwo fun iku ni fifon eyo kan

[14] ti won gbe ile ati apata soke, ti won si run mejeeji womuwomu ni rirun ee kan

[15] ni ojo yen ni Isele maa sele

[16] Ati pe sanmo yo faya perepere. O si maa fuye gege ni ojo yen

[17] Awon molaika si maa wa ni awon egbeegbe re. Ati pe ni ojo yen, loke won, awon (molaika) mejo ni won maa ru Ite Oluwa re

[18] Ni ojo yen, won yoo maa seri yin wa (fun isiro-ise). Ko si nii si asiri yin kan t’o maa pamo (fun Wa)

[19] Nitori naa, ni ti eni ti won ba fun ni tira re ni owo otun re, o maa so pe: "E gba, e ka tira mi

[20] Dajudaju emi ti mo amodaju pe dajudaju emi yoo ba isiro-ise mi pade

[21] Nitori naa, o maa wa ninu isemi t’o maa yonu si

[22] ninu Ogba Idera giga

[23] Awon eso re (si) wa ni arowoto

[24] E je, ki e si mu pelu igbadun nitori ohun ti e ti siwaju ninu awon ojo ti o ti re koja

[25] Ni ti eni ti won ba si fun ni tira re ni owo osi re, o maa wi pe: "Haa! Ki won si ma fun mi ni tira mi! mejeeji lo maa sele si won nitori pe owo osi ni alaigbagbo maa ti bo inu igba-aya re bo si eyin re lati fi gba iwe ise re

[26] Ati pe emi ko mo ohun ti isiro-ise mi je

[27] Haa! Ki iku si je opin (oro eda)

[28] Dukia mi ko si ro mi loro

[29] Agbara mi si ti parun

[30] E mu un, ki e de e ni owo mo orun

[31] Leyin naa, inu ina Jehim ni ki e mu un wo

[32] Leyin naa, inu ewon ti gigun re je aadorin gigun thar‘u ni ki e ki i si

[33] Dajudaju oun ki i gbagbo ninu Allahu, Atobi

[34] Ki i si gba eniyan niyanju lati bo awon mekunnu

[35] Nitori naa, ko nii si ore imule kan fun un nibi yii ni oni

[36] Ko si nii si ounje kan (fun un) bi ko se (ounje) awoyunweje

[37] Ko si eni ti o maa je e bi ko se awon elese

[38] Nitori naa, Emi n bura pelu ohun ti e n foju ri

[39] ati ohun ti e o foju ri

[40] Dajudaju al-Ƙur’an ni oro (ti A fi ran) Ojise, alapon-onle

[41] Ki i se oro elewi. Ohun ti e gbagbo kere pupo

[42] Ki i si se oro adabigba. Die le n lo ninu iranti

[43] Won so o kale lati odo Oluwa gbogbo eda

[44] Ti o ba je pe (Anabi) da adapa apa kan oro naa mo Wa ni

[45] Awa iba gba a mu lowo otun

[46] Leyin naa, Awa iba ja isan orun re

[47] Ko si si eni kan ninu yin ti o maa gba a sile lowo (Wa)

[48] Dajudaju (al-Ƙur’an) ni iranti fun awon oluberu (Allahu)

[49] Dajudaju Awa si mo pe awon t’o n pe al-Ƙur’an niro wa ninu yin

[50] Dajudaju al-Ƙur’an maa je abamo fun awon alaigbagbo

[51] Dajudaju al-Ƙur’an ni ododo t’o daju

[52] Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa Re, Atobi

Àwọn Ọ̀nà Ìgòkè

Surah 70

[1] Onibeeere kan beere nipa iya t’o maa sele

[2] si awon alaigbagbo. Ko si si eni ti o maa di i lowo

[3] lodo Allahu, Onipo-aye giga

[4] Awon molaika ati molaika Jibril n gunke wa si odo Re ninu ojo kan ti odiwon re je oke meji aabo (ti e ba fe rin in)

[5] Nitori naa, se suuru ni suuru t’o rewa

[6] Dajudaju won n wo (iya naa) ni ohun t’o jinna

[7] A si n wo o ni ohun t’o sunmo

[8] (Ojo naa ni) ojo ti sanmo yo da bi ide t’o yo

[9] awon apata yo si da bi egbon owu-irun

[10] ore imule kan ko si nii beere ore imule (re)

[11] Won maa ri ara won (won si maa dara won mo). Elese si maa fe ki oun fi awon omo re serapada emi ara re nibi Iya ni ojo yen

[12] Iyawo re ati arakunrin re

[13] ati awon ebi re t’o pa ti, ti awon si n gba a sodo nile aye

[14] ati gbogbo eni t’o wa lori ile aye patapata, (o maa fe fi won serapada emi ara re nibi Iya). Leyin naa, (o maa fe) ki Allahu gba oun la (ninu iya Ina)

[15] Rara! Dajudaju (o maa wo) ina Latho (ina t’o n jo fofo)

[16] O maa bo awo ori toro

[17] (Ina) yo maa ke si eni t’o keyin si (igbagbo ododo), ti o si takete si i

[18] o ko (oro) jo, o si fi pamo (ko na an fun esin)

[19] Dajudaju eniyan, A seda re ni alailokan, okanjua

[20] Nigba ti aburu ba fowo ba a, o maa kanra gogo

[21] Nigba ti owo re ba si te oore, o maa yahun

[22] Ayafi awon olukirun

[23] awon oludunnimo irun won

[24] awon t’o mo ojuse (won) ninu dukia won

[25] si alagbe ati eni ti A se arisiki ni eewo fun

[26] awon t’o n gba ojo esan gbo ni ododo

[27] awon t’o n paya iya Oluwa won

[28] dajudaju iya Oluwa won ko see fayabale si

[29] awon t’o n so abe won

[30] ayafi lodo awon iyawo won tabi erubinrin won ni won ko ti le je eni-eebu

[31] nitori naa, eni keni t’o ba n wa nnkan miiran leyin iyen, awon wonyen ni awon olutayo-enu ala

[32] awon t’o n so agbafipamo won ati adehun won

[33] awon t’o n duro ti ijerii won

[34] ati awon t’o n so awon irun won

[35] Awon wonyen ni alapon-onle ninu awon Ogba Idera

[36] Ki lo mu awon ti ko gbagbo ti ara won ko bale niwaju re

[37] ti won si jokoo ni isori isori si owo otun ati owo osi (re)

[38] Se eni kookan ninu won n jerankan pe A oo mu oun wo inu Ogba Idera ni

[39] Rara o! Dajudaju Awa seda won lati inu ohun ti won mo

[40] Nitori naa, Emi n bura pelu Oluwa awon ibuyo oorun ati awon ibuwo oorun , dajudaju Awa ni Alagbara

[41] lati le fi awon t’o dara ju won lo paaro won. Ko si si eni t’o le ko agara ba Wa

[42] Nitori naa, fi won sile ki won maa so isokuso (won), ki won si maa sere titi won yoo fi pade ojo won ti A n se ni adehun fun won

[43] Ojo ti won yoo sare jade werewere lati inu awon saree, won yo si da bi eni pe won n yara lo sidii ohun afojusun kan

[44] Oju won yoo wale. Iyepere maa bo won mole. Ojo yen ni eyi ti A n se ni adehun fun won

Núhù

Surah 71

[1] Dajudaju Awa ran (Anabi) Nuh nise si ijo re pe: "Sekilo fun ijo re siwaju ki iya eleta-elero to de ba won

[2] O so pe: "Eyin ijo mi, dajudaju emi ni olukilo ponnbele fun yin

[3] pe ki e josin fun Allahu, ki e beru Re, ki e si tele mi

[4] (Allahu) maa saforijin awon ese yin fun yin. O si maa lo yin lara titi di gbedeke akoko kan. Dajudaju akoko (iku ti) Allahu (ko mo eda), nigba ti o ba de, won ko nii sun un siwaju ti o ba je pe e mo

[5] O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi pe ijo mi ni oru ati ni osan

[6] Ipe mi ko si se alekun kan fun won ayafi sisa seyin (fun ododo)

[7] Ati pe igbakigba ti mo ba pe won pe ki O le forijin won, won n fi omonika won di eti won, won n yiso won bori, won n taku (sori ese), won si n segberaga gan-an

[8] Leyin naa, dajudaju emi pe won pelu ohun oke

[9] Leyin naa, dajudaju emi kede fun won, mo si tun pe won ni ida konko

[10] Mo si so pe, e toro aforijin ni odo Oluwa yin, dajudaju O n je Alaforijin

[11] O maa rojo fun yin ni ojo pupo

[12] O maa fi awon dukia ati awon omokunrin ran yin lowo. O maa se awon ogba oko fun yin. O si maa se awon odo fun yin

[13] Ki lo mu yin ti e ko paya titobi Allahu

[14] O si kuku seda yin lati irisi kan si omiran (ninu oyun)

[15] Se e o ri bi Allahu se da awon sanmo meje ni ipele ipele ni

[16] O si se osupa ni imole sinu won. O tun se oorun ni atupa

[17] Allahu mu yin jade lati ara erupe ile

[18] Leyin naa, O maa da yin pada sinu re. O si maa mu yin jade taara

[19] Allahu se ile fun yin ni ite

[20] nitori ki e le to awon oju ona fife gbegede lori re

[21] (Anabi) Nuh so pe: "Oluwa mi, dajudaju won yapa mi. Won si tele eni ti dukia re ati omo re ko se alekun kan fun bi ko se ofo

[22] Won si dete ni ete t’o tobi

[23] Won si wi pe: "E ma se fi awon orisa yin sile. E ma se fi orisa Wadd, Suwa‘u, Yeguth, Ye‘uƙ ati Nasr sile

[24] Dajudaju won ti ko opolopo sina. (Oluwa mi) ma se je ki awon alabosi lekun ni kini kan bi ko se isina

[25] Nitori ese won, won te won ri sinu omi. Won si maa fi won sinu Ina. Won ko si nii ri awon alaranse fun won leyin Allahu

[26] (Anabi) Nuh tun so pe: "Oluwa mi, ma se fi eni kan kan ninu awon alaigbagbo sile lori ile

[27] Dajudaju ti Iwo ba fi won sile, won yoo ko isina ba awon eru Re. Won ko si nii bi omo kan afi eni buruku, alaigbagbo

[28] Oluwa mi forijin emi, awon obi mi mejeeji ati eni t’o ba wo inu ile mi (ti o je) onigbagbo ododo ati awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin. Ma si salekun kan fun awon alabosi afi iparun

Àwọn Jinnì

Surah 72

[1] So pe: "Won fi imisi ranse si mi pe dajudaju ijo kan ninu awon alujannu teti (si al-Ƙur’an)." Won si so pe: "Dajudaju awa gbo al-Ƙur’an iyanu

[2] O n setosona sibi imona. Nitori naa, a gba a gbo. Awa ko si nii fi eni kan kan se akegbe fun Oluwa wa

[3] Ati pe dajudaju titobi Oluwa wa ga. Ko fi eni kan kan se aya ati omo

[4] Dajudaju omugo ninu wa maa n so isokuso nipa Allahu

[5] Dajudaju awa si n ro pe eniyan ati alujannu ko nii pa iro mo Allahu ni

[6] Ati pe dajudaju awon okunrin kan ninu eniyan maa n fi awon okunrin kan ninu awon alujannu wa aabo. Awon alujannu si se alekun aburu fun won

[7] Dajudaju awon alujannu lero gege bi eyin eniyan naa se lero pe Allahu ko nii gbe eni kan kan dide (leyin iku)

[8] Dajudaju awa wa (oro ayogbo) wa si sanmo, a si ba a ti o ti kun fun awon eso t’o lagbara ati awon ogunna

[9] Dajudaju awa maa n jokoo sibe ni awon ibudo kan fun gbigbo oro. Sugbon eni t’o ba joro gbo lasiko yii, o maa ri ogunna t’o ti lugo de e

[10] Dajudaju awa ko si mo boya aburu ni won gba lero pelu awon t’o wa lori ile tabi Oluwa won gbero imona fun won

[11] Dajudaju awon eni rere wa ninu wa. Awon miiran yato si iyen tun wa ninu wa. A wa loju ona (esin) otooto

[12] Dajudaju awa mo amodaju pe awa ko le mori bo mo Allahu lowo lori ile. Awa ko si le sa mo On lowo

[13] Dajudaju nigba ti a gbo nipa imona (lati inu al-Ƙur’an), a gba a gbo. Nitori naa, enikeni ti o ba gba Oluwa re gbo, ki o ma beru adinku (esan rere) ati (alekun) aburu

[14] Dajudaju awon musulumi wa ninu wa. Awon arufin naa wa ninu wa. Nitori naa, enikeni ti o ba se ’Islam, awon wonyen ni won se awari imona

[15] Ni ti awon arufin, awon ni won maa je igi ikona fun ina Jahanamo.”

[16] Ati pe ti o ba je pe won duro sinsin loju ona (’Islam) ni, dajudaju Awa iba fun won ni omi pupo mu

[17] Nitori ki A le fi dan won wo ni. Enikeni ti o ba gbunri kuro nibi iranti Oluwa re, O maa mu un wo inu iya inira

[18] Dajudaju awon mosalasi n je ti Allahu. Nitori naa, e o gbodo fi pe eni kan pelu Allahu

[19] Dajudaju nigba ti erusin Allahu dide duro t’o n pe Allahu, awon alujannu fee maa difun-un-unfun lodo re (lati teti si al-Ƙur’an)

[20] So pe: "Oluwa mi ni mo n pe. Ati pe emi ko nii so eni kan kan di akegbe fun Un

[21] So pe: "Dajudaju emi ko ni ikapa lori inira ati imona fun yin

[22] So pe: "Dajudaju emi, ko si eni kan t’o le gba mi la lodo Allahu. Emi ko si ri ibusasi kan leyin Re

[23] Afi (ki ng se) ikede (t’o wa) lati odo Allahu ati awon ise Re (t’O fi ran mi). Enikeni t’o ba yapa Allahu ati Ojise Re, dajudaju ina Jahanamo n be fun un. Olusegbere ni won ninu re titi laelae

[24] (Alaigbagbo ko nii ye sai gbagbo) titi di igba ti won yoo fi ri ohun ti A n se ni adehun fun won. Nigba naa, won yoo mo ta ni o le julo ni alaranse, ti o si kere julo ni onka

[25] So pe: "Emi ko mo boya ohun ti Won n se ni adehun fun yin ti sunmo tabi Oluwa mi yoo fun un ni akoko (t’o jinna)

[26] Onimo-ikoko, ko si fi (imo) ikoko Re han eni kan

[27] ayafi eni ti O salesa t’o je Ojise. Dajudaju O n mu eso kan rin niwaju Ojise naa ati leyin re

[28] nitori ki O le safi han pe won ti je awon ise Oluwa won. Ati pe Allahu fi imo rokiri ka ohun ti n be lodo won. O si so onka gbogbo nnkan

Ẹni tí a fi wé

Surah 73

[1] Iwo oludasobora

[2] Dide (kirun) ni oru ayafi fun igba die

[3] Lo ilaji re tabi din die ku ninu re

[4] Tabi fi kun un. Ki o si ke al-Ƙur’an ni pelepele

[5] Dajudaju Awa maa gbe oro t’o lagbara fun o

[6] Dajudaju idide kirun loru, o wonu okan julo, o si dara julo fun kike (al-Ƙur’an)

[7] Dajudaju ise pupo wa fun o ni osan

[8] Ranti oruko Oluwa re. Ki o si da okan ko O patapata

[9] Oluwa ibuyo oorun ati ibuwo oorun, ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, mu Un ni Alafeyinti

[10] Ki o si se suuru lori ohun ti won n wi. Pa won ti ni ipati t’o rewa

[11] Fi Mi da awon olupe-ododo-niro, awon oloro. Ki o si lora fun won fun igba die

[12] Dajudaju sekeseke ati Ina Jehim n be lodo Wa

[13] Ounje hafunhafun ati iya eleta-elero (tun wa fun won)

[14] Ni ojo ti ile ati awon apata yoo maa mi titi pelu ohun igbe lile. Awon apata si maa di yanrin ti won kojo ti won tuka

[15] Dajudaju Awa ran Ojise kan nise si yin (ti o je) olujerii lori yin gege bi A se ran Ojise kan nise si Fir‘aon

[16] Sugbon Fir‘aon yapa Ojise naa. A si gba a mu ni igbamu lile

[17] Ti eyin ba sai gbagbo, bawo ni eyin yoo se beru ojo kan t’o maa mu awon omode hewu

[18] Sanmo si maa faya perepere ninu re. Adehun Re je ohun ti o maa se

[19] Dajudaju eyi ni iranti. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu oju ona kan to de odo Oluwa re

[20] Dajudaju Oluwa re mo pe dajudaju iwo n dide kirun fun ohun t’o kere si ilata meji oru tabi ilaji re tabi ilata re. Igun kan ninu awon t’o wa pelu re (naa n se bee). Allahu l’O n sodiwon oru ati osan. O si mo pe e ko le so o. Nitori naa, O ti da a pada si fifuye fun yin. Nitori naa, e ke ohun ti o ba rorun (fun yin) ninu al-Ƙur’an. O mo pe awon alaisan yoo wa ninu yin. Awon miiran si n ririn ajo lori-ile, ti won n wa ninu oore Allahu. Awon miiran si n jagun fun esin Allahu. Nitori naa, e ke ohun ti o ba rorun (fun yin) ninu re. E kirun (oran-an-yan). E yo Zakah. Ki e si ya Allahu ni dukia t’o dara. Ohunkohun ti e ba ti siwaju fun emi ara yin ninu ohun rere, eyin yoo ba a lodo Allahu ni ohun rere ati ni ohun ti o tobi julo ni esan. E toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun

Ẹni tí a fi aṣọ bora

Surah 74

[1] Iwo oludasobora

[2] Dide ki o sekilo

[3] Oluwa re si ni ki o gbe titobi fun

[4] Aso re ni ki o fo mo

[5] Orisa ni ki o jinna si

[6] Ma se tore nitori ki o le ri pupo gba

[7] Oluwa re ni ki o se suuru fun

[8] Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde

[9] iyen, ni ojo yen, ni ojo inira

[10] ti ko nii rorun fun awon alaigbagbo

[11] Fi Mi da eni ti Mo da ni oun nikan

[12] Mo si fun un ni opolopo dukia

[13] ati awon omokunrin t’o n be pelu re

[14] Mo si se aye nirorun fun un gan-an

[15] Leyin naa, o tun n jerankan pe ki Ng se alekun

[16] Rara o! Dajudaju o je alatako si awon ayah Wa

[17] Emi yoo la iya ponkeponke bo o lorun (ninu Ina)

[18] Dajudaju o ronu (lodi nipa al-Ƙur’an). O si pinnu (oro kan ninu emi re)

[19] Won si sebi le e nipa bi o se pinnu

[20] Leyin naa, Won tun sebi le e nipa bi o se pinnu

[21] Leyin naa, o wo sun

[22] Leyin naa, o faju ro, o si diju magbari

[23] Leyin naa, o peyin da, o si segberaga

[24] O si wi pe: "Ki ni eyi bi ko se idan atowodowo

[25] Ki ni eyi bi ko se oro abara

[26] Emi yoo fi sinu ina Saƙor

[27] Ki l’o mu o mo ohun t’o n je ina Saƙor

[28] (Saƙor) ko nii se e ku, ko si nii pa a ti

[29] O maa jo awo ara di dudu

[30] (Awon molaika) mokandinlogun ni eso re

[31] Awa ko se eni kan ni eso Ina afi awon molaika. Awa ko si se onka won (bee) bi ko se (nitori ki o le je) adanwo fun awon t’o sai gbagbo, ati nitori ki awon ti A fun ni Tira le ni amodaju ati nitori ki awon ti won gbagbo ni ododo le lekun ni igbagbo ododo. (O ri bee) nitori ki awon ti A fun ni Tira ati awon onigbagbo ododo ma baa seyemeji ati nitori ki awon ti arun wa ninu okan won ati awon alaigbagbo le wi pe: "Ki ni Allahu gba lero pelu apejuwe yii?" Bayen ni Allahu se n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Ko si si eni ti o mo awon omo ogun Oluwa re afi Oun naa. (Ina Saƙor) ko si je kini kan bi ko se iranti fun abara

[32] E gbo! Allahu bura pelu osupa

[33] O tun bura pelu ale nigba ti o ba lo

[34] O tun bura pelu owuro nigba ti ojumo ba mo

[35] Dajudaju (ina Saƙor) ni okan ninu (awon adanwo) t’o tobi

[36] (O je) ikilo fun abara

[37] Fun eni ti o ba fe ninu yin lati te siwaju tabi lati fa seyin

[38] Emi kookan ni oniduuro fun ohun t’o se nise

[39] Ayafi awon ero owo otun

[40] Won yoo maa bira won leere oro ninu awon Ogba Idera

[41] nipa awon elese pe

[42] Ki ni o mu yin wo inu ina Saƙor

[43] Won yoo wi pe: "Awa ko si ninu awon olukirun ni

[44] Awa ko si si ninu awon t’o n bo awon mekunnu

[45] Awa si maa n so isokuso pelu awon onisokuso

[46] Ati pe awa maa n pe Ojo esan niro

[47] titi iku fi de ba wa

[48] Ipe awon olusipe ko si nii se won ni anfaani

[49] Ki lo mu won na ti won n gbunri kuro nibi iranti

[50] bi eni pe awon ni ketekete t’o n sa lo

[51] t’o sa fun kinihun

[52] Rara, nse ni enikookan ninu won n fe ki A fun oun naa ni Tira ti o maa see te han awon eniyan (bii ti al-Ƙur’an)

[53] Rara. Won ko paya orun ni

[54] E gbo! Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti

[55] Nitori naa, eni ti o ba fe ko ranti re

[56] Won ko si nii ranti (al-Ƙur’an) afi ti Allahu ba fe. (Allahu) Oun l’a gbodo beru. Oun l’o si laforijin

Àjíǹde

Surah 75

[1] Emi (Allahu) n bura pelu Ojo Ajinde

[2] Mo tun n bura pelu emi t’o maa dara re lebi

[3] Se eniyan lero pe A o nii ko awon eegun re jo ni

[4] Rara o. A lagbara lati to eegun omonika re dogba

[5] Sugbon eniyan gbero lati pe (Ojo Ajinde) t’o n be niwaju re niro

[6] O n beere pe: "Igba wo ni Ojo Ajinde

[7] Nigba ti oju ba ko mona

[8] ati (nigba) ti osupa ba wookun

[9] ati (nigba) ti A ba pa oorun ati osupa po mora won

[10] eniyan yoo wi ni ojo yen pe: "Nibo ni ibusasi wa

[11] Rara, ko si ibusasi

[12] Odo Oluwa re ni ibuduro ni ojo yen

[13] Won maa fun eniyan ni iro ni ojo yen nipa ohun t’o ti siwaju (ninu ise re) ati ohun t’o fi keyin (ninu oripa ise re)

[14] Sebi eniyan da ara re mo

[15] ibaa mu awon awawi re wa

[16] Ma se gbe ahon re si imisi lati kanju ke e

[17] Dajudaju Awa l’A maa se ikojo re (sinu okan re) ati kike re

[18] Nigba ti A ba n ke e (fun o), ki o si maa tele kike re

[19] Leyin naa, dajudaju Awa l’A maa se alaye re fun o

[20] E gbo! Nse l’e nifee aye

[21] E si n pa orun ti

[22] Awon oju kan ni ojo yen yoo tutu (fun idunnu)

[23] Oluwa won ni won yoo maa wo

[24] Awon oju kan ni ojo yen si maa baje

[25] (Oju naa) yoo mo daju pe Won maa fi aburu kan ohun

[26] E gbo! Nigba ti emi ba de gogongo

[27] A si maa so pe: "Nje olofo pipe kan wa bi (ti o maa gba a sile lowo iku)

[28] O si maa da a loju pe dajudaju ipinya aye ti de

[29] Ojugun yo si lomo ojugun

[30] Odo Oluwa re si ni wiwa eda lo ni ojo yen

[31] Ko kuku gba ododo gbo, ko si kirun

[32] Sugbon o pe ododo niro. O si keyin si i

[33] Leyin naa, o lo si odo awon eniyan re, o si n se faari

[34] Egbe ni fun o, egbe ni se

[35] Leyin naa, egbe ni fun o, egbe si se

[36] Se eniyan lero pe A maa fi oun sile lasan ni

[37] Se ko ti je ato moni ti won da jade sinu apoluke ni

[38] Leyin naa, o di eje didi. (Allahu) si seda (re). O si se e t’o dogba jale leeyan

[39] (Allahu) si se iran meji jade lati inu re, ako ati abo

[40] Nje Eni ti O se iyen ko nii ni agbara lati ji awon oku dide bi

Àkókò

Surah 76

[1] Sebi akoko kan ninu igba ti re koja lori eniyan ti (eniyan) ko je kini kan ti won n daruko

[2] Dajudaju Awa seda eniyan lati ara ato t’o ropo mora won (lati ara okunrin ati obinrin), ki A le dan an wo. A si se e ni olugbo, oluriran

[3] Dajudaju A fi ona mo on; O le je oludupe, o si le je alaimoore

[4] Dajudaju Awa pese awon ewon, ajaga ati Ina sile de awon alaigbagbo

[5] Dajudaju awon eni rere, won yoo maa mu omi kan ninu ife. Ohun ti A popo mo (omi naa) ni kafura

[6] Omi iseleru kan ni, ti awon erusin Allahu yoo maa mu, ti won yo si maa mu un san jade daadaa (si ibi ti won ba fe)

[7] Won n mu eje won se. Won si n paya ojo kan, ti aburu re je ohun ti o maa fonka gan-an

[8] Tohun ti bi won se ni ife si (oro to), won n fun mekunnu, omo orukan ati eru ni ounje je

[9] (Won si n so pe:) "Nitori Oju rere Allahu (nikan) l’a fi n fun yin ni ounje; awa ko si gbero esan tabi idupe kan lati odo yin

[10] Dajudaju awa n paya ni odo Oluwa wa ojo kan ti (eda yoo) faju ro koko

[11] Nitori naa, Allahu yoo so won nibi aburu ojo yen. O si maa fun won ni itutu oju ati idunnu

[12] O si maa san won ni esan Ogba Idera ati aso alari nitori pe won se suuru

[13] Won yoo maa rogbo ku sori awon ibusun won. Won ko si nii ri oorun tabi otutu

[14] Awon ooji (inu Ogba Idera) yoo sunmo won. A si maa mu awon eso ibe sunmo arowoto won ni ti sisunmo

[15] Ati pe won yoo maa gbe ife imumi nla ti won se lati ara fadaka ati awon ife imumi kekere ti o je alawo kaa kiri odo won

[16] Ife alawo ti won se lati ara fadaka ni (won). A si se won niwon-niwon (ti o se weku ohun ti won fe mu)

[17] Ati pe won yoo maa fun won ni ife oti kan mu ninu (Ogba Idera). Ohun ti A popo mo (oti naa) ni atale

[18] Ninu Ogba Idera (won yoo tun maa mu) omi iseleru kan, ti A n pe ni omi salsabil

[19] Awon odokunrin ti ko nii gbo yo si maa lo bo laaarin won. Nigba ti iwo ba si ri won, iwo yoo ka won kun okuta olowo iyebiye ti won tan kale

[20] Nigba ti iwo ba si wo ibe yen (ninu Ogba Idera), iwo yoo ri idera ati ola t’o tobi

[21] Aso ara won ni aso aran felefele alawo eweko ati aso alagbaaa. A si maa fi egba-owo onifadaka se won ni oso. Oluwa won yo si fun won ni ohun mimu mimo mu

[22] Dajudaju eyi je esan fun yin. Ise yin si ja si ope

[23] Dajudaju Awa l’A so al-Ƙur’an kale fun o diedie

[24] Nitori naa, se suuru fun idajo Oluwa re. Ma se tele elese tabi alaimoore kan ninu won

[25] Ranti oruko Oluwa re ni aaro ati ni asale

[26] Ati ni oru, fori kanle fun Un. Ki o si safomo fun Un ni oru fun igba pipe

[27] Dajudaju awon wonyi feran aye. Won si n pa ojo t’o wuwo ti seyin won

[28] Awa l’A seda won. A si se won ni alagbara. Nigba ti A ba si fe, A oo fi iru won (miiran) paaro won ni ti ipaaro

[29] Dajudaju eyi ni iranti. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu oju ona to si odo Oluwa re

[30] Eyin ko si nii fe (kini kan) afi ti Allahu ba fe. Dajudaju Allahu n je Onimo, Ologbon

[31] O maa fi eni ti o ba fe sinu ike re. (Ni ti) awon alabosi, O si pese iya eleta-elero sile de won

Àwọn Ońṣẹ́

Surah 77

[1] Allahu bura pelu awon ategun t’o n sare ni telentele

[2] O bura pelu awon iji ategun t’o n ja

[3] O bura pelu awon ategun t’o n tu esujo ka

[4] O bura pelu awon t’o n sepinya laaarin ododo ati iro

[5] O tun bura pelu awon molaika t’o n mu iranti wa (ba awon Ojise)

[6] (Iranti naa je) awijare tabi ikilo

[7] Dajudaju ohun ti A se ni adehun fun yin kuku maa sele

[8] Nitori naa, nigba ti won ba pa (imole) irawo re

[9] ati nigba ti won ba si sanmo sile gbagada

[10] ati nigba ti won ba ku awon apata danu

[11] ati nigba ti won ba fun awon Ojise ni asiko lati kojo, (Akoko naa ti de niyen)

[12] Ojo wo ni won so (awon isele wonyi) ro fun na

[13] Fun ojo ipinya (laaarin awon eda) ni

[14] Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo ipinya

[15] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[16] Nje Awa ko ti pa awon eni akoko re bi

[17] Leyin naa, A si maa fi awon eni Ikeyin tele won (ninu iparun)

[18] Bayen ni A o ti se pelu awon elese

[19] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[20] Se A o seda yin lati inu omi lile yepere bi

[21] Leyin naa, A fi sinu aye aabo (iyen, ile-omo)

[22] titi di gbedeke akoko kan ti A ti mo (iyen, ojo ibimo)

[23] A si ni ikapa ati ayanmo (lori re). (Awa si ni) Olukapa ati Olupebubu eda t’o dara

[24] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[25] Nje Awa ko se ile ni ohun t’o n ko eda jo mora won

[26] (iyen) awon alaaye ati awon oku

[27] A si fi awon apata gbagidi giga-giga sinu re. A si fun yin ni omi didun mu

[28] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[29] E maa lo si ibi ti e n pe niro

[30] E maa lo si ibi eefin eleka meta

[31] Ki i se iboji tutu. Ko si nii ro won loro ninu ijofofo Ina

[32] Dajudaju (Ina naa) yoo maa ju etapara (re soke t’o maa da) bi peteesi

[33] (O maa da) bi awon rakunmi alawo omi osan

[34] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[35] Eyi ni ojo ti won ko nii soro

[36] A o si nii yonda (oro siso) fun won, ambosibosi pe won yoo mu awawi wa

[37] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[38] Eyi ni ojo ipinya. Awa yo si ko eyin ati awon eni akoko jo

[39] Ti e ba ni ete kan lowo, e dete si Mi wo

[40] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[41] Dajudaju awon oluberu Allahu yoo wa nibi iboji ati awon omi iseleru

[42] ati awon eso eyi ti won ba n fe

[43] E je, ki e si mu pelu igbadun nitori ohun ti e n se nise

[44] Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)

[45] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[46] E je, ki e si gbadun fun igba die. Dajudaju elese ni yin

[47] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[48] Nigba ti won ba so fun won pe ki won kirun, won ko nii kirun

[49] Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro

[50] Nigba naa, oro wo ni won yoo gbagbo leyin re

Ìròyìn

Surah 78

[1] Nipa ki ni won n bira won leere na

[2] Nipa iro ikoko nla ni

[3] eyi ti won n yapa enu si

[4] Rara! Won n bo wa mo

[5] Leyin naa, ni ti ododo won n bo wa mo

[6] Nje Awa ko se ile ni ite bi

[7] ati awon apata ni eekan (fun ile)

[8] A si seda yin ni orisirisi (ako ati abo)

[9] A se oorun yin ni isinmi

[10] A tun se ale ni ibora

[11] A tun se osan ni (asiko fun) wiwa ije-imu

[12] A tun mo sanmo meje t’o lagbara soke yin

[13] A tun se oorun ni imole t’o n tan gbola

[14] Ati pe A so omi t’o n bo telera won kale lati inu awon esujo

[15] nitori ki A le fi mu koro eso ati irugbin jade

[16] pelu awon ogba t’o kun digbi fun nnkan oko

[17] Dajudaju ojo ipinya, o ni gbedeke akoko kan

[18] (Iyen ni) ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. Eyin yo si maa wa nijo-nijo

[19] Won si maa si sanmo sile. O si maa di awon ilekun

[20] Won maa mu awon apata rin (bo si aye miiran). O si maa di ahunpeena

[21] Dajudaju ina Jahanamo, o lugo sile loju ona

[22] (O je) ibugbe fun awon alakoyo

[23] Won yoo maa gbe inu re fun igba gbooro

[24] Won ko nii ri itura tabi ohun mimu kan towo ninu re

[25] ayafi omi gbigbona ati awoyunweje

[26] (O je) esan t’o se weku (ise won)

[27] Dajudaju won ki i reti isiro-ise

[28] Won si pe awon ayah Wa niro gan-an

[29] Gbogbo nnkan si ni A ti se akosile re sinu Tira kan

[30] Nitori naa, e to (iya) wo. A o si nii se alekun kan fun yin bi ko se iya

[31] Dajudaju igbala wa fun awon oluberu (Allahu)

[32] Awon ogba ati eso ajara

[33] ati awon olomoge, ti won ko jura won lo lojo-ori

[34] ati ife oti t’o kun denu (ni esan won)

[35] Won ko nii gbo isokuso ati oro iro ninu re

[36] (O je) esan lati odo Oluwa re, (o si je) ore ni ibamu si isiro-ise (won)

[37] (Esan naa wa lati odo) Oluwa awon sanmo, ile ati ohun t’o wa laaarin mejeeji, Ajoke-aye. Won ko si ni ikapa oro lodo Re

[38] Ojo ti molaika Jibril ati awon molaika (miiran) yoo duro ni owoowo. Won ko si nii soro afi eni ti Ajoke-aye ba yonda fun. Onitoun si maa soro t’o se weku

[39] Iyen ni ojo ododo. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu ona to maa gba seri pada si odo Oluwa re pon (ni ti ironupiwada)

[40] Dajudaju A fi iya t’o sunmo se ikilo fun yin. Ojo ti eniyan yoo maa wo ohun ti o ti siwaju, alaigbagbo yo si wi pe: "Yee, emi iba si je erupe, (emi iba la ninu iya)

Àwọn tó ń fà jáde

Surah 79

[1] Allahu bura pelu awon molaika t’o n fi ona ele gba emi awon alaigbagbo

[2] O tun bura pelu awon molaika t’o n fi ona ero gba emi awon onigbagbo ododo

[3] O tun bura pelu awon molaika t’o n yara gaga nibi ase Re

[4] O tun bura pelu awon molaika t’o maa siwaju emi awon onigbagbo ododo wonu Ogba Idera taara

[5] O tun bura pelu awon molaika t’o n seto ile aye

[6] Ni ojo ti ifon akoko fun opin aye maa mi gbogbo aye titi pelu ohun igbe

[7] Ifon keji fun Ajinde si maa tele e

[8] Awon okan yoo maa gbon pepe ni ojo yen

[9] Oju won yo si wale ni ti iyepere

[10] Won yoo wi pe: "Se Won tun maa da wa pada si ibere isemi (bii taye ni)

[11] Se nigba ti a ti di eegun t’o kefun tan

[12] Won wi pe: "Idapada ofo niyen nigba naa (fun eni t’o pe e niro)

[13] Nitori naa, igbe eyo kan si ni

[14] Nigba naa ni won yoo bara won lori ile gbansasa

[15] Nje oro (Anabi) Musa ti de odo re

[16] (Ranti) nigba ti Oluwa re pe e ni afonifoji mimo, Tuwa

[17] Lo ba Fir‘aon, dajudaju o ti tayo enu-ala

[18] Ki o si so pe: "Nje o maa safomo ara re (kuro ninu aigbagbo) bi

[19] Ki emi si fi ona mo o de odo Oluwa re. Nitori naa, ki o paya (Re)

[20] O si fi ami t’o tobi han an

[21] (Amo) o pe e lopuro. O si yapa re

[22] Leyin naa, o keyin si i. O si n sise (tako o)

[23] O ko (awon eniyan) jo, o si ke gbajari

[24] O si wi pe: "Emi ni oluwa yin, eni giga julo

[25] Nitori naa, Allahu gba a mu pelu iya ikeyin ati akoko (nipa oro enu re ikeyin yii ati akoko)

[26] Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun eni t’o n paya (Allahu)

[27] Se eyin le lagbara julo ni iseda ni tabi sanmo ti Allahu mo

[28] Allahu gbe aja re ga soke. O si se e ni pipe t’o gun rege

[29] O se oru re ni dudu. O si fa iyaleta re yo jade

[30] Ati ile, O te e perese leyin iyen

[31] O mu omi re ati irugbin re jade lati inu re

[32] Ati awon apata, O fi idi won mule sinsin

[33] Igbadun ni fun yin ati fun awon eran-osin yin

[34] Sugbon nigba ti iparun nla ba de

[35] ni ojo ti eniyan yoo ranti ohun t’o se nise

[36] Won si maa fi Ina han kedere fun (gbogbo) eni t’o riran

[37] Nitori naa, ni ti eni t’o ba tayo enu-ala

[38] ti o tun gbe ajulo fun isemi aye

[39] dajudaju ina Jehim, ohun ni ibugbe (re)

[40] Ni ti eni ti o ba paya iduro niwaju Oluwa re, ti o tun ko ife-inu fun emi (ara re)

[41] dajudaju Ogba Idera, ohun ni ibugbe (re)

[42] Won n bi o leere nipa Akoko naa pe: "Igba wo l’o maa sele

[43] Ona wo ni iwo le fi ni (imo) iranti re na

[44] Odo Oluwa re ni opin imo nipa re wa

[45] Iwo kuku ni olukilo fun eni t’o n paya re

[46] Ni ojo ti won maa ri i, won maa da bi eni pe won ko lo tayo irole tabi iyaleta (ojo) kan lo (nile aye)

Ó dojú rú

Surah 80

[1] (Anabi s.a.w.) faju ro, o si peyin da

[2] nitori pe afoju wa ba a

[3] Ki si l’o maa fi mo o pe o see se ki o safomo (ara re kuro ninu aigbagbo)

[4] tabi ki o gbo iranti, ki iranti naa si se e ni anfaani

[5] Ni ti eni ti o ka ara re kun oloro

[6] oun ni iwo teti si

[7] Ko si si ese fun o bi ko ba se afomo (ara re kuro ninu aigbagbo)

[8] Ni ti eni ti o si wa ba o, t’o n yara gaga (si iranti, iyen afoju)

[9] ti o si n paya (Allahu)

[10] iwo ko si kobi ara si i

[11] Rara (ko to bee). Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti

[12] Nitori naa, eni ti o ba fe ki o ranti re

[13] (Al-Ƙur’an) wa ninu awon takada alapon-onle

[14] A gbe e ga, A si se e ni mimo

[15] ni owo awon onkotia (iyen, awon molaika)

[16] awon alapon-onle, awon eni rere

[17] Won ti fi eniyan gegun-un (nipa) bi o se je alaimoore julo

[18] Ki si ni Allahu fi seda re

[19] Ninu ato l’O ti seda re. O si pebubu (eya-ara) re

[20] Leyin naa, O se ona atiwaye ni irorun fun un

[21] Leyin naa, O maa pa a. O si maa fi sinu saree

[22] Leyin naa, nigba ti Allahu ba fe, O maa gbe e dide

[23] E gbo, eniyan ko ti i se nnkan ti Allahu pa lase fun un

[24] Nitori naa, ki eniyan woye si ounje re

[25] Dajudaju Awa n ro ojo ni pupo

[26] Leyin naa, A mu ile san kankan

[27] A si mu koro eso hu jade lati inu re

[28] ati eso ajara ati kannafuru

[29] ati igi ororo Zaetun ati dabinu

[30] ati awon ogba t’o kun fun igi

[31] ati awon eso (miiran) pelu ewe ti eranko n je, (A mu won hu jade)

[32] (Won je nnkan) igbadun fun eyin ati awon eran-osin yin

[33] Nigba ti fifon sinu iwo nigba keji ba sele

[34] ni ojo ti eniyan yoo sa fun arakunrin re

[35] ati iya re pelu baba re

[36] ati iyawo re pelu awon omo re

[37] Eni kookan won ni ojo yen l’o ti ni oran t’o maa to o o ran

[38] Awon oju kan lojo yen yoo mole

[39] Won yo maa rerin-in, won yo si maa dunnu

[40] Awon oju kan lojo yen ni eruku yo si bo mole

[41] Okunkun yo si bo won mole

[42] Awon wonyen, awon ni alaigbagbo, elese

Ìdìtẹ́palẹ̀

Surah 81

[1] Nigba ti Won ba ka oorun korobojo danu

[2] ati nigba ti awon irawo ba ja bo kaakiri

[3] ati nigba ti Won ba mu awon apata rin (kuro ni aye won, ti won ku won danu)

[4] ati nigba ti won ba pa awon rakunmi aboyun ti

[5] ati nigba ti Won ba ko awon eranko jo

[6] ati nigba ti Won ba mu awon agbami odo gbina

[7] ati nigba ti Won ba so awon emi po mora won, (eni rere pelu eni rere, eni ibi pelu eni ibi)

[8] ati nigba ti omobinrin ti won bo mole laaye ba beere pe

[9] ese wo ni won pa oun fun

[10] ati nigba ti Won ba si awon takada (ise eda) sile

[11] ati nigba ti Won ba ka sanmo kuro loke

[12] ati nigba ti won ba mu ina Jehim jo fofo

[13] ati nigba ti Won ba sun Ogba Idera mo (awon onigbagbo ododo)

[14] (nigba naa ni) emi (kookan) yoo mo ohun ti o mu wa (ninu ise ire ati ise ibi)

[15] Nitori naa, Emi (Allahu) n bura pelu awon irawo t’o n yo ni ale, t’o n wookun ni osan

[16] (iyen) awon irawo t’o n rin lo rin bo, t’o n wookun si ibuwo won

[17] Mo tun bura pelu ale nigba ti o ba lo

[18] Mo tun bura pelu owuro nigba ti o ba mole

[19] Dajudaju (al-Ƙur’an) ni oro (ti A fi ran Jibril) Ojise, alapon-onle

[20] alagbara, eni pataki ni odo Eni t’O ni Ite-ola

[21] eni ti won n tele ase re nibe yen (ninu sanmo), olufokantan

[22] Ati pe eni yin (Anabi Muhammad s.a.w.) ki i se were

[23] O kuku ri i ninu ofurufu kedere

[24] Ati pe ki i se ahun (tabi eni-afurasi) lori iro ikoko (ti A fi ranse si i)

[25] Al-Ƙur’an ki i si se oro (ti A fi ran) Esu, eni eko

[26] Nitori naa, ibo l’e n lo

[27] Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda

[28] (O wa) fun eni ti o ba fe ninu yin lati duro deede

[29] Eyin ko si nii fe (lati duro deede) ayafi ti Allahu ba fe, Oluwa gbogbo eda

Ìlà

Surah 82

[1] Nigba ti sanmo ba fa ya perepere

[2] ati nigba ti awon irawo ba ja bo kaakiri

[3] ati nigba ti awon ibudo ba san jara won

[4] ati (nigba ti A ba ta ile soke), ti A si mu awon oku jade (laaye) lati inu awon saree

[5] (nigba naa ni) emi kookan yoo mo ohun ti o ti siwaju (ninu ise re) ati ohun ti o fi seyin (ninu oripa ise re)

[6] Iwo eniyan, ki ni o tan o je nipa Oluwa re, Alapon-onle

[7] Eni t’O seda re? O seda re ni pipe. O si mu o dogba jale leeyan

[8] O to eya ara re papo sinu eyikeyii aworan ti O fe

[9] Ni ti ododo, nse l’e n pe Ojo esan niro

[10] Dajudaju awon eso si wa ni odo yin

[11] (Won je) alapon-onle, onkowe-ise eda

[12] Won mo ohun ti e n se nise

[13] Dajudaju awon eni rere yoo kuku wa ninu igbadun

[14] Dajudaju awon eni ibi yo si kuku wa ninu ina Jehim

[15] Won yoo wo inu re ni Ojo esan

[16] Won ko si nii kuro ninu re

[17] Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo esan

[18] Leyin naa, ki ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo esan

[19] (Ojo esan ni) ojo ti emi kan ko nii kapa kini kan fun emi kan. Gbogbo ase ojo yen si n je ti Allahu

Ìdẹ́rùbà

Surah 83

[1] Egbe ni fun awon oludin-osuwon-ku

[2] awon (ontaja) t’o je pe nigba ti won ba won nnkan lodo awon eniyan, won a gba a ni ekun

[3] nigba ti awon (ontaja naa) ba si lo iwon fun awon (onraja) tabi lo osuwon fun won, won yoo din in ku

[4] Se awon wonyen ko mo daju pe dajudaju A maa gbe won dide

[5] ni Ojo nla kan

[6] Ni ojo ti awon eniyan yoo dide naro fun Oluwa gbogbo eda

[7] Bee ni, dajudaju iwe ise awon eni ibi kuku wa ninu Sijjin

[8] Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je Sijjin

[9] Iwe ti won ti ko ise aburu eda sinu re (ti won si fi pamo sinu ile keje ni Sijjin)

[10] Ni ojo yen, egbe ni fun awon olupe-ododo- niro

[11] awon t’o n pe Ojo esan niro

[12] Ko si si eni t’o n pe e niro afi gbogbo alakoyo, elese

[13] Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa wi pe: "Awon akosile alo awon eni akoko (niwonyi)

[14] Rara ko ri bee, amo ohun ti won n se nise ibi l’o joba lori okan won

[15] Ni ti ododo, dajudaju won yoo wa ninu gaga, won ko si nii ri Oluwa won ni ojo yen

[16] Leyin naa, dajudaju won yoo wo inu ina Jehim

[17] Leyin naa, won maa so (fun won) pe: "Eyi ni ohun ti e n pe niro

[18] Bee ni. Dajudaju iwe ise awon eni rere wa ninu ‘illiyyun

[19] Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je ‘illiyyun

[20] Iwe ti won ti ko ise rere eda sinu re (ti won si fi pamo si oke sanmo ni ‘illiyyun)

[21] Awon (molaika) ti won sunmo Allahu n jerii si i

[22] Dajudaju awon eni rere maa wa ninu igbadun

[23] Won yoo maa woran lori awon ibusun

[24] Iwo yoo da itutu oju igbadun mo ninu oju won

[25] Won yoo maa fun won mu ninu oti onideeri

[26] Alumisiki ni (oorun) ipari re. Ki awon alapaantete sapantete ninu iyen

[27] Tesnim ni won yoo maa popo (mo oti naa)

[28] (Tesnim ni) omi iseleru kan, ti awon olusunmo (Allahu) yoo maa mu

[29] Dajudaju awon t’o dese, won maa n fi awon t’o gbagbo ni ododo rerin-in

[30] Nigba ti won ba gba egbe won koja, (awon adese) yoo maa seju sira won ni ti yeye

[31] Nigba ti won ba si pada si odo awon eniyan won, won a pada ti won yoo maa se faari

[32] Ati pe nigba ti won ba ri (awon onigbagbo ododo) won a wi pe: "Dajudaju awon wonyi ni olusina

[33] Awa ko si ran won nise oluso si won

[34] Nitori naa, ni oni awon t’o gbagbo ni ododo yoo fi awon alaigbagbo rerin-in

[35] Won yoo maa woran lori awon ibusun

[36] Sebi won ti fi ohun ti awon alaigbagbo n se nise san won lesan (bayii)

Ṣíṣẹ́

Surah 84

[1] Nigba ti sanmo ba faya perepere

[2] o gbo, o si tele ase Oluwa re ni. O si di dandan fun un lati se bee –

[3] ati nigba ti A ba fe ile loju

[4] o maa ju ohun ti o wa ninu re sita, o si maa pa sofo

[5] – o gbo, o si tele ase Oluwa re ni. O si di dandan fun un lati se bee – (ni ojo yen ni eda maa ri ise owo re)

[6] Iwo eniyan dajudaju iwo n se ise karakara ni ise asepade Oluwa re. O si maa mu un pade Re

[7] Nitori naa, ni ti eni ti won ba fun ni iwe ise re ni owo otun re

[8] laipe A maa se isiro-ise (re) ni isiro irorun

[9] O si maa pada si odo awon eniyan re (ninu Ogba Idera) leni idunnu

[10] Ni ti eni ti won ba si fun ni iwe ise re lati eyin re

[11] laipe o maa kigbe iparun

[12] O si maa wo inu Ina t’o n jo fofo

[13] Dajudaju o ti wa laaarin awon eniyan re leni idunnu (si aigbagbo nile aye)

[14] Dajudaju o lero pe oun ko nii pada (si odo Allahu ni)

[15] Rara (o maa pada). Dajudaju Oluwa re je Oluriran nipa re

[16] Nitori naa, Emi (Allahu) n bura pelu awonpapa

[17] Mo tun bura pelu oru ati ohun ti o ko jo sinu re

[18] Mo tun bura pelu osupa nigba ti o ba degba (pelu imole re)

[19] Dajudaju eyin yoo maa bo sinu wahala kan lati inu wahala kan

[20] Ki l’o se won na ti won ko fi gbagbo ni ododo

[21] Nigba ti won ba si ke al-Ƙur’an fun won, won ko nii fori kanle

[22] Rara, nse ni awon t’o sai gbagbo n pe e niro

[23] Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo (sinu okan won)

[24] Nitori naa, fun won ni iro iya eleta-elero

[25] Ayafi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, esan ti ko nii pin n be fun won

Àwọn Ìràwọ̀

Surah 85

[1] (Allahu) bura pelu sanmo ti awon ibuso (oorun, osupa ati awon irawo) wa ninu re

[2] O tun bura pelu ojo ti won se ni adehun

[3] O tun bura pelu olujerii ati ohun t’o jerii si

[4] A sebi le awon t’o gbe koto (ina)

[5] (iyen) ina ti won n fi igi ko (ninu koto)

[6] (Ranti) nigba ti won jokoo si itosi re

[7] Won si n wo ohun ti won n se fun awon onigbagbo ododo

[8] Ko si si kini kan ti won tori re je won niya bi ko se pe won ni igbagbo ododo ninu Allahu, Alagbara, Olope

[9] Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile. Allahu si ni Elerii lori gbogbo nnkan

[10] Dajudaju awon t’o fi inira kan awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, leyin naa ti won ko ronu piwada, iya ina Jahanamo n be fun won. Iya ina t’o n jo si wa fun won

[11] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, tiwon ni awon Ogba Idera kan, ti awon odo n san ni isale re. Iyen si ni erenje nla

[12] Dajudaju igbamu ti Oluwa re ma le

[13] Dajudaju Oun ni O pile (eda), O si maa da (eda) pada (fun ajinde)

[14] Oun ni Alaforijin, Ololufe (eda)

[15] Oun l’O ni Ite-ola, Eni-owo julo

[16] Oluse-ohun-t’O-ba-fe

[17] Sebi iro awon omo ogun ti de odo re

[18] (omo ogun) Fir‘aon ati (ijo) Thamud

[19] Sibesibe awon t’o sai gbagbo si n pe ododo niro

[20] Allahu si yi won ka leyin won

[21] Amo sa, ohun (ti A fi ranse si o ni) al-Ƙur’an alapon-onle

[22] ti o wa ninu walaa ti A n so

Ìràwọ̀ Òwúrọ̀

Surah 86

[1] (Allahu) bura pelu sanmo ati Toriƙ

[2] Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Toriƙ

[3] Irawo ti imole re n tan roro (ni ale ni)

[4] Ko si emi kan afi ki eso kan wa fun un (ninu awon molaika)

[5] Nitori naa, ki eniyan woye si ohun ti A fi seda re

[6] Won seda re lati inu omi t’o n tu jade kookoo

[7] O n jade lati aarin ibadi okunrin ati awon efonha igba-aya obinrin

[8] Dajudaju Allahu ni Alagbara lori idapada re

[9] ni ojo ti won maa se ayewo awon (ise) asepamo

[10] Nigba naa, ko nii si agbara tabi alaranse kan fun un

[11] Allahu bura pelu sanmo t’o n ro ojo ni odoodun

[12] O tun bura pelu ile t’o n san kankan (fun hihujade eso)

[13] Dajudaju al-Ƙur’an ni oro-ipinya (laaarin ododo ati iro)

[14] Ki i si se awada

[15] Dajudaju won n dete gan-an

[16] Emi naa si n dete gan-an

[17] Nitori naa, lora fun awon alaigbagbo. Lo won lara se fun igba die

Olú Ọ̀gá Ògo

Surah 87

[1] Safomo fun oruko Oluwa re, Eni giga julo

[2] Eni ti O da eda. O si se (orikee-rikee re) ni dogbadogba

[3] Eni ti O yan kadara (fun eda). O si to o sona

[4] Eni ti O mu koriko tutu (hu) jade

[5] O si so o di gbigbe t’o dudu

[6] Awa yoo maa ke (al-Ƙur’an) fun o. Iwo ko si nii gbagbe

[7] Ayafi ohun ti Allahu ba fe. Dajudaju O mo gbangba ati ohun t’o pamo

[8] Awa yo si se ise rere ni irorun fun o

[9] Nitori naa, seranti ni aye ti iranti ti wulo

[10] Eni ti o maa paya (Allahu) maa lo iranti

[11] Olori-buruku si maa takete si i

[12] (Oun si ni) eni ti o maa wo inu Ina t’o tobi

[13] Leyin naa, ko nii ku sinu re, ko si nii semi (alaafia)

[14] Dajudaju eni ti o ba safomo (okan re) ti jere

[15] O tun ranti oruko Oluwa re, o si kirun

[16] Rara, nse l’e n gbe ajulo fun isemi aye

[17] Orun si loore julo, o si maa wa titi laelae

[18] Dajudaju eyi wa ninu awon takada akoko

[19] takada (Anabi) ’Ibrohim ati (Anabi) Musa

Ìbòrí-lẹ́ṣẹ́

Surah 88

[1] Nje oro nipa ohun t’o maa bo eda mole ti de odo re

[2] Awon oju kan yoo wale (ni ti iyepere) ni ojo yen

[3] Onise asekudorogbo (ni won nile aye)

[4] Won maa wo inu Ina t’o gbona janjan (ni orun)

[5] Won si maa fun (won) ni omi gbigbona mu

[6] Ko si ounje kan fun won ayafi igi elegun-un gbigbe

[7] Ko nii mu won sanra. Ko si nii ro won loro ninu ebi

[8] Awon oju kan yo si kun fun igbadun ni ojo yen

[9] nitori pe (o) yonu si (esan) ise re

[10] (O maa) wa ninu Ogba Idera giga

[11] Won ko nii gbo isokuso ninu re

[12] Omi iseleru t’o n san wa ninu re

[13] Awon ibusun ti won gbe soke wa ninu re

[14] ati awon ife imumi ti won gbe kale (si arowoto won)

[15] ati awon irori ti won to si egbe ara won

[16] ati awon ite ateeka

[17] Nitori naa, se won ko wo rakunmi, bi A ti seda re ni

[18] ati sanmo, bi A ti se gbe e soke

[19] ati apata, bi A ti se gbe e naro (sinu ile)

[20] ati ile, bi A ti se te e sile ni gbansasa

[21] Nitori naa, seranti. Iwo kuku ni oluseranti

[22] Iwo ki i se ajeni-nipa lori won

[23] afi eni ti o ba peyinda (si ododo), ti o si sai gbagbo

[24] Allahu si maa je e niya t’o tobi julo

[25] Dajudaju odo Wa ni abo won wa

[26] Leyin naa, dajudaju Awa l’A maa se isiro-ise won

Àfẹ̀mọ́júmọ́

Surah 89

[1] Allahu bura pelu afemojumo

[2] O tun bura pelu awon oru mewaa kan

[3] O tun bura pelu meji ati eyo

[4] O tun bura pelu oru nigba ti o ba lo (ti o ba de)

[5] Nje ibura wa ninu iyen fun onilaakaye

[6] Se o o ri bi Oluwa re ti se oro ara ‘Ad

[7] (iyen awon iran) ’Irom, awon omiran

[8] awon ti A o da iru won mo sinu ilu

[9] Ati awon Thamud ti won gbe (ile igbe) sinu apata ninu afonifoji

[10] ati Fir‘aon eleekan (iya)

[11] (Awon wonyi ni) awon t’o tayo enu-ala ninu ilu

[12] Won si se ibaje pupo sinu re

[13] Oluwa re si rojo iya le won lori

[14] Dajudaju Oluwa re wa ni ibuso (ise eda)

[15] Nitori naa, ni ti eniyan, nigba ti Oluwa re ba dan an wo, ti O pon on le, ti O si se idera fun un, nigba naa o maa wi pe: "Oluwa mi ti pon mi le

[16] Sugbon nigba ti O ba dan an wo, ti O gan arisiki re le e lowo, nigba naa o maa wi pe: "Oluwa mi ti yepere mi

[17] Rara, ko ri bee. Amo, eyin ko saponle omo-orukan

[18] Ati pe eyin ko gbera yin longbe lati fun mekunnu ni ounje

[19] E tun n je ogun ni ijekuje

[20] Ati pe e nifee si dukia ni ife pupo

[21] Rara, (ko ye ko ri bee). Nigba ti won ba mi ile titi ni mimi titi (t’o run womuwomu, ti ko si koto, ti ko si gelemo)

[22] (ti) Oluwa re de pelu awon molaika ni owoowo owoowo

[23] ni ojo yen ni won maa mu ina Jahanamo wa. Ni ojo yen, eniyan yoo ranti (oro ara re). Bawo si ni iranti naa se le wulo fun un

[24] O maa wi pe: "Yee, emi iba ti ti (ise rere) siwaju fun isemi mi

[25] Ni ojo yen, eni kan ko le fi iya je (eda) bi iru iya (ti) Allahu (yoo fi je e)

[26] Eni kan ko si le de (eda) ni igbekun bi iru igbekun (ti) Allahu (yoo fi de e)

[27] Iwo emi olufokanbale

[28] pada si odo Oluwa re ni oluyonu, eni iyonu

[29] Nitori naa, wole saaarin awon erusin Mi

[30] Wo inu Ogba Idera Mi

Ìlú

Surah 90

[1] Emi (Allahu) bura pelu ilu yii

[2] Iwo si ni eto si ilu yii (lati jagun ninu re)

[3] (Mo tun) bura pelu obi ati ohun t’o bi

[4] Dajudaju A seda eniyan sinu isoro

[5] Se o n lero pe eni kan ko ni agbara lori oun ni

[6] O (si) n wi pe: "Emi ti bana dukia opolopo (lati fi tako Anabi s.a.w)

[7] Se o n lero pe eni kan ko ri oun ni

[8] Se A ko se oju meji fun un

[9] Ati ahon pelu ete meji (ti A se fun un)

[10] A si fi ona meji mo on

[11] Ko si mu akaba igbala gun

[12] Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je akaba igbala

[13] (Ohun ni) titu eru sile loko eru

[14] Tabi fifun eniyan ni ounje ni ojo ebi

[15] (O le je) omo-orukan ninu ebi

[16] tabi mekunnu, eni ileele

[17] Leyin naa, ki o wa ninu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won n gbara won niyanju suuru sise, ti won si tun n gbara won niyanju aanu sise

[18] Awon wonyen ni ero owo otun

[19] Awon t’o si sai gbagbo ninu awon ayah Wa, awon ni ero owo osi

[20] A maa ti awon ilekun Ina pa mo won lori patapata

Oòrùn

Surah 91

[1] (Allahu) bura pelu oorun ati iyaleta re

[2] O tun bura pelu osupa nigba ti o ba (yo) tele (oorun)

[3] O tun bura pelu osan nigba ti o ba mu imole ba okunkun oru

[4] O tun bura pelu ale nigba ti o ba bo osan mole

[5] O tun bura pelu sanmo ati Eni ti O mo on

[6] O tun bura pelu ile ati Eni ti O te e kale

[7] O tun bura pelu emi (eniyan) ati Eni ti O se (orikee re) dogba

[8] O si fi ese (ti emi le da) ati iberu re mo on

[9] Enikeni ti o ba safomo (emi ara) re (nibi ese), o ma ti jere

[10] Enikeni ti o ba fi (iwa ese) ba emi (ara) re je, o ma ti padanu

[11] Ijo Thamud pe ododo niro nipa itayo enu-ala won

[12] (Ranti) nigba ti eni ti ori re buru julo ninu won sare dide (lati gun rakunmi pa)

[13] Nigba naa, Ojise Allahu so fun won pe: "(E fi) abo rakunmi Allahu ati omi re (sile)

[14] Won pe e niro. Won si gun (rakunmi) pa. Nitori naa, Oluwa won pa won re nitori ese won. O si fi iparun naa kari won

[15] (Eni t’o gun rakunmi pa) ko si paya ikangun oro won

Òru

Surah 92

[1] (Allahu) bura pelu ale nigba ti (ile) ba su

[2] O tun bura pelu osan nigba ti (osan) ba pon

[3] O tun bura pelu Eni ti O da ako ati abo

[4] Dajudaju ise yin, otooto ni

[5] Ni ti eni ti o ba tore, ti o si beru (Allahu)

[6] (ti) o tun pe esan rere ni ododo

[7] A si maa se ise rere ni irorun fun un

[8] Ni ti eni ti o ba yahun, ti o si ri ara re leni t’o roro tayo esan orun

[9] (ti) o tun pe esan rere ni iro

[10] A si maa se ise aburu ni irorun fun un

[11] Dukia re ko si nii ro o loro nigba ti o ba ja bo (sinu Ina)

[12] Dajudaju tiWa ni (lati salaye) imona

[13] Ati pe dajudaju tiWa ni orun ati aye

[14] Nitori naa, Mo ti fi Ina elejo fofo kilo fun yin

[15] Ko si eni ti o maa wo inu re afi olori buruku

[16] eni ti o pe ododo niro, ti o si keyin si i

[17] Won si maa gbe (Ina) jinna si oluberu (Allahu)

[18] eni t’o n fi dukia re tore, ti o n safomo (re)

[19] Ko si si oore idera kan ti (o ni lokan) lati gba ni esan ni odo enikeni

[20] bi ko se pe lati fi wa oju rere Oluwa re, Eni Giga julo

[21] Laipe o si maa yonu (si esan re)

Àwọn Wákàtí Òwúrọ̀

Surah 93

[1] (Allahu bura pelu) iyaleta

[2] O tun bura pelu ale nigba ti (ile) ba su

[3] Oluwa re ko pa o ti, ko si binu si o

[4] Dajudaju orun loore fun o ju aye lo

[5] Dajudaju laipe Oluwa re maa fun o ni (oore pupo ni orun). Nitori naa, o si maa yonu si i

[6] Se (Allahu) ko ri o ni omo-orukan ni? O si fun o ni ibugbe

[7] O si ri o ni alaimona (iyen siwaju isokale imisi). O si fi ona mo o

[8] O tun ri o ni alaini, O si ro o loro

[9] Nitori naa, ni ti omo-orukan, ma se je gaba (le e lori)

[10] Ni ti alagbe, ma si se jagbe (mo on)

[11] Ni ti idera Oluwa re, so o jade

Ìtura

Surah 94

[1] Se A o sipaya igba-aya re fun o bi

[2] A si gbe ese re kuro lorun re

[3] eyi ti o wo o lorun. amo ti onitoun pada gba ’Islam ibaa je pe o gba a ni owuro

[4] A si gbe iranti oruko re ga fun o

[5] Nitori naa, dajudaju idekun wa leyin inira

[6] Dajudaju idekun wa leyin inira se

[7] Nitori naa, nigba ti o ba buse (lori okan), gbiyanju (omiran)

[8] Odo Oluwa re si ni ki o soju kokoro oore si

Ọ̀pọ̀tọ́

Surah 95

[1] Allahu bura pelu eso tin ati eso zaetun

[2] O tun bura pelu apata Sinin

[3] O tun bura pelu ilu ifayabale yii

[4] Dajudaju A seda eniyan pelu irisi t’o dara julo

[5] Leyin naa, A maa da a pada si isale patapata (ninu Ina)

[6] Ayafi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. Nitori naa, esan ti ko nii pin (ti ko nii pedin) n be fun won

[7] Ta l’o tun n pe o ni opuro nipa Ojo esan leyin (oro yii)

[8] Se Allahu ko ni Eni t’O mo ejo da julo ninu awon adajo ni

Ẹ̀jẹ̀ Dídì

Surah 96

[1] Ke (al-Ƙur’an) pelu oruko Oluwa re, Eni ti O da eda

[2] O seda eniyan lati ara eje didi

[3] Ke e. Oluwa re ni Alapon-onle julo

[4] Eni ti O fi imo nipa gege ikowe mo eniyan

[5] O fi imo ti eniyan ko mo mo on

[6] Ni ti ododo, dajudaju eniyan kuku n tayo enu-ala

[7] nitori pe o rira re ni oloro

[8] Dajudaju odo Oluwa re ni abo eda

[9] So fun mi nipa eni t’o n ko

[10] fun erusin kan nigba ti (erusin naa) kirun

[11] So fun mi (nipa esan re) ti o ba je pe o wa lori imona (’Islam)

[12] tabi pe o pase iberu (Allahu)

[13] So fun mi (nipa iya re) ti o ba je pe o pe ododo niro, ti o si keyin si i

[14] Se ko mo pe dajudaju Allahu n ri (oun ni)

[15] Bee ni (Allahu n ri i.) Dajudaju ti ko ba jawo (nibi didi i lowo), dajudaju A maa fi aaso ori re wo o (sinu Ina)

[16] aaso ori opuro, elese

[17] Nitori naa, ki o pe awon olubajokoo re

[18] Awa maa pe awon molaika eso Ina

[19] Rara o, ma se tele tire. Fori kanle (ki o kirun), ki o sunmo (Allahu)

Àṣẹ

Surah 97

[1] Dajudaju Awa so al-Ƙur’an kale ninu Oru Abiyi

[2] Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Oru Abiyi

[3] Oru Abiyi loore ju egberun osu lo

[4] Awon molaika ati Jibril yo si maa sokale ninu oru naa pelu ase Oluwa won fun gbogbo oro eda kookan

[5] Alaafia ni oru naa titi di asiko afemojumo

Ẹ̀rí Tó Yanju

Surah 98

[1] Awon t’o sai gbagbo ninu awon ahlul-kitab ati awon osebo, won ko nii kuro ninu aigbagbo won titi di igba ti eri t’o yanju yo fi maa de odo won

[2] Ojise kan lati odo Allahu yo (si) maa ke awon takada mimo

[3] Awon iwe ofin t’o fese rinle si wa ninu re

[4] Awon ti A fun ni tira ko si di ijo otooto afi leyin ti eri t’o yanju de ba won

[5] Awa ko si pa won ni ase kan bi ko se pe ki won josin fun Allahu (ki won je) oluse-afomo esin fun Un, oluduro deede. Ki won kirun, ki won si yo Zakah. Iyen si ni esin t’o fese rinle

[6] Dajudaju awon t’o sai gbagbo (wonyi) ninu awon ahlul-kitab ati awon osebo, won yoo wa ninu Ina. Olusegbere ni won ninu re. Awon wonyen, awon ni eda t’o buru julo

[7] Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo (iyen, awon musulumi), ti won si se awon ise rere, awon wonyen, awon ni eda t’o dara julo

[8] Esan won ni odo Oluwa won ni awon Ogba Idera gbere, ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Allahu yonu si won. Awon naa yonu si (ohun ti Allahu fun won). Iyen wa fun enikeni ti o ba paya Oluwa re

Ìsẹ̀lẹ̀

Surah 99

[1] Nigba ti won ba mi ile titi ni imititi re

[2] ati (nigba) ti ile ba tu awon eru t’o wuwo ninu re jade

[3] eniyan yo si wi pe: "Ki l’o mu un

[4] Ni ojo yen ni (ile) yoo soro nipa awon iro re (ti eda gbe ori ile se)

[5] Nitori pe dajudaju Oluwa re l’O fun un ni ase (lati soro)

[6] Ni ojo yen, awon eniyan yoo maa gba ona otooto lo nitori ki won le fi awon ise won han won

[7] Nitori naa, eni ti o ba se ise rere ni odiwon omo ina-igun, o maa ri i

[8] Eni ti o ba si se ise aburu ni odiwon omo ina-igun, o maa ri i

Àwọn Agẹṣinjagun

Surah 100

[1] Allahu bura pelu awon esin t’o n sare t’o n mi helehele ni oju-ogun

[2] O tun bura pelu awon esin ti patako ese won n sana (nibi ere sisa)

[3] O tun bura pelu awon esin t’o n kolu ota esin ni owuro kutukutu

[4] Won si fi (patako ese won) tu eruku (ile ota) soke

[5] Won tun be gija papo pelu re saaarin akojo ota

[6] Dajudaju eniyan ni alaimoore si Oluwa re

[7] Dajudaju Allahu si n je Elerii lori iyen

[8] Ati pe dajudaju eniyan le gan-an nibi ife oore aye

[9] Se ko mo pe nigba ti won ba tu ohun t’o wa ninu saree jade (fun ajinde)

[10] ti won si tu ohun t’o wa ninu igba-aya eda sita patapata

[11] dajudaju Oluwa won ni Alamotan nipa won ni Ojo yen

Àjàkálẹ̀-àrùn

Surah 101

[1] Akoko ijaya

[2] Ki ni Akoko ijaya

[3] Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je Akoko ijaya

[4] (Ohun ni) ojo ti eniyan yo da bi afopina ti won fonka sita

[5] awon apata yo si da bi owu ti won gbon danu

[6] Nitori naa, ni ti eni ti osuwon (ise rere) re ba te won

[7] o si maa wa ninu isemi t’o yonu si

[8] Ni ti eni ti osuwon (ise rere) re ba si fuye

[9] Hawiyah si ni ibugbe re

[10] Ki si o mu o mo ohun t’o n je bee

[11] (Ohun ni) Ina gbigbona gan-an

Ìdíje nínú ayé

Surah 102

[1] Wiwa oore aye ni opolopo fun iyanran sise ti ko airoju fesin ba yin

[2] titi e fi wo inu saree

[3] Rara (ko ye ko ri bee, amo) laipe e maa mo

[4] Leyin naa, ni ododo laipe e maa mo

[5] Bee ni, ti o ba je pe e ni imo amodaju ni (eyin iba ti se bee)

[6] Dajudaju e maa ri ina Jehim

[7] Leyin naa, dajudaju e maa ri i ni aridaju

[8] Leyin naa, dajudaju ni ojo yen won maa bi yin leere nipa igbadun (aye yii)

Ọjọ́ tí ń kọjá lọ

Surah 103

[1] Allahu bura pelu akoko irole aye

[2] Dajudaju eniyan wa ninu ofo

[3] Ayafi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won so asotele ododo laaarin ara won, ti won si tun so asotele suuru laaarin ara won

Olùbanijẹ́

Surah 104

[1] Egbe ni fun gbogbo abuniloju-eni, abunileyin-eni

[2] eni ti o ko owo jo, ti o si ka a lakatunka (lai na an fesin)

[3] O n lero pe dajudaju dukia re yoo mu un se gbere (nile aye)

[4] Rara (ko ri bee). Dajudaju won maa ku u loko sinu Hutomoh ni

[5] Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Hutomoh

[6] (Ohun ni) Ina Allahu ti won n ko (t’o n jo geregere)

[7] eyi ti o maa jo (eda) wo inu okan lo

[8] Dajudaju won maa ti (awon ilekun) Ina pa mo won lori patapata

[9] (Won maa wa) laaarin awon opo kiribiti giga (ninu Ina)

Erin

Surah 105

[1] Se o o ri bi Oluwa re ti se oro ijo elerin ni

[2] Se ko so ete won di ofo bi

[3] O si ran awon eye nikoniko si won

[4] Won n ju won ni okuta amo (t’o ti gbana sara)

[5] O si so won di bii erunrun koriko ajeku gbigbe

Quréshì

Surah 106

[1] (Ike ni lati odo Allahu) fun idile Ƙuraes lati wa papo ninu aabo

[2] (Ike ni se lati odo Allahu) fun won lati wa papo ninu aabo lori irin-ajo ni igba otutu ati igba ooru

[3] Nitori naa, ki won josin fun Oluwa Ile (Ka‘bah) yii

[4] Eni ti O fun won ni jije (ni asiko) ebi. O si fi won lokan bale ninu ipaya

Àwọn Ìṣeun Rere Kéékèèké

Surah 107

[1] So fun mi nipa eni t’o n pe Ojo Esan niro

[2] Iyen ni eni t’o n le omo-orukan danu

[3] Ko si nii gbiyanju lati bo mekunnu

[4] Egbe ni fun awon (munaafiki) t’o n kirun; ko tumo si “ohun t’o n run eniyan”. Amo itumo “irun” ni “ohun t’o n run ese olukirun” nitori pe ti olukirun ba ti se aluwala ni o ti san gbogbo awon ese weere ti o ti fi awon orikee ara re se siwaju. Bakan naa

[5] awon t’o n gbagbe lati kirun won ni asiko re

[6] awon t’o n se sekarimi

[7] ati pe won n hanna ohun elo (fun awon eniyan)

Ọ̀pọ̀lọpọ̀

Surah 108

[1] Dajudaju Awa fun o ni opolopo oore

[2] Nitori naa, kirun fun Oluwa re, ki o si gunran (fun Un)

[3] Dajudaju, eni t’o n binu re, oun ni ko nii leyin

Àwọn Káfírì

Surah 109

[1] So pe: "Eyin alaigbagbo

[2] Emi ko nii josin fun ohun ti e n josin fun

[3] Eyin naa ko josin fun Eni ti mo n josin fun

[4] Emi ko nii josin fun ohun ti e josin fun se

[5] Eyin naa ko ku josin fun Eni ti mo n josin fun

[6] Tiyin ni esin yin, temi si ni esin mi

Ìrànlọ́wọ́

Surah 110

[1] Nigba ti aranse Allahu (lori ota esin) ati sisi ilu (Mokkah) ba sele

[2] ti o si ri awon eniyan ti won wonu esin Allahu nijonijo

[3] nitori naa, safomo pelu idupe fun Oluwa re. Ki o si toro aforijin lodo Re. Dajudaju O n je Olugba-ironupiwada

Ọwọ́ Iná

Surah 111

[1] Owo Abu-Lahab mejeeji ti sofo. Oun naa si sofo

[2] Awon dukia re ati ohun ti o se nise (iyen, awon omo re) ko si nii ro o loro (nibi iya)

[3] O si maa wo inu Ina elejo fofo

[4] Ati iyawo re, alaaaru-igi-isepe elegun-un, (o maa wona)

[5] Igba-ope ponponran maa wa ni orun re (ninu Ina)

Ìwà Mímọ́

Surah 112

[1] So pe: "Oun ni Allahu, Okan soso

[2] Allahu ni Asiwaju (ti eda ni bukata si, ti Oun ko si ni bukata si won)

[3] Ko bimo. Won ko si bi I

[4] Ko si si eni kan ti o jo O." eyi ni a mo si “robbu-ssamowat wal-’ard wa mo baenahumo”. Idi niyi ti a o fi tumo “Allahu” si “Olohun”. Ninu ede Yoruba ko fee si itumo ti a fokan bale si fun oro-oruko nla naa “Allahu” afi lilo oro-oruko kan eyi ti awon Yoruba maa n lo ni ojoun ana fun “Olohun”. Sise bee si maa mu ariyanjiyan lowo. Nitori naa

Àfẹ̀mọ́júmọ́

Surah 113

[1] So pe: "Mo sa di Oluwa owuro kutukutu

[2] nibi aburu ohun ti O da

[3] ati nibi aburu oru nigba ti o ba sookun

[4] ati nibi aburu awon (opidan) t’o n fenu fategun tuetue sinu awon onde

[5] ati nibi aburu onilara nigba ti o ba se ilara

Aráyé

Surah 114

[1] So pe: "Mo sa di Oluwa awon eniyan

[2] Oba awon eniyan

[3] Olohun awon eniyan

[4] nibi aburu (Esu) oniroyiroyi, olusaseyin (fun eni t’o ba daruko Allah)

[5] (Esu ni) eni ti o n ko royiroyi sinu awon okan eniyan

[6] (Esu naa) wa ninu alujannu ati eniyan